O lè di alábápín àwọn àtèjáde wa nípa pí parí fọ́ọ̀mù yii
Ní Ìjọ Òtítọ́ Bíbélì , ìdàgbàsókè àti ìtésíwájú rẹ nínú ẹ̀mí ló jẹ́ ọ̀kúnkúndùn sí wa. A kí ọ káàbọ̀.
Ní Ìjọ Òtítọ́ Bíbélì , ìdàgbàsókè àti ìtésíwájú rẹ nínú ẹ̀mí ló jẹ́ ọ̀kúnkúndùn sí wa. A kí ọ káàbọ̀.
Ọjọ: Okudu 13, 2021 | Nọmba: Vol. 10, No. 6
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Okudu 2021. Adura mi si ni pe ki a pa iwọ ati idile rẹ mọ lati ri ire ti Ọlọrun yoo mu wa fun orilẹ-ede yi, ni orukọ Jesu. Amin.
Dafidi, ninu ọkan ninu awọn orin rẹ, sọ pe, “Ṣugbọn emi ti gbagbọ lati ri ire Oluwa ni ilẹ alaaye. Duro de Oluwa; ki o si tuju ka, yoo si mu ọ ni aya le: mo ni duro de Oluwa.” (Saamu 27:13-14) Ki ni igbagbọ ọkunriin yi? Igbagbọ rẹ ni pe yoo ri ire Oluwa ni ilẹ alaaye. Ki si ni idi ti o fi igbagbọ lọna yi? Idi ni pe o n duro de Oluwa ti ko ki i jani kulẹ.
Bi a ti ṣe ri ninu iwe mimọ, gẹgẹ bi ọdọmọkurin, Dafidi dojukọ inunibini ti o le koko lati ọdọ Sọọlu, ti o jẹ ọba lori Isiraẹli ni akoko ti a n wi yi. Nitorina, oun, awọn jagunjagun rẹ ati awọn ẹbi wọn ni lati ma fi gbogbo igba sa lati ibikan si ibomiran; wọn ko si le gbe aye bi awọn eniyan gidi ṣe n gbe aye. Igba kan tilẹ wa, ẹwẹ, ti a sọ ina si agọ wọn ti wọn n lo fi igba diẹ, ti awọn ara Amaleki si ko gbogbo awọn iyawo ati ọmọ wọn lọ. Eyi si ni awọn jagunjagun lara tobẹẹ gẹẹ ti wọn fi bẹrẹ si ni sọrọ nipa lilẹ ni okuta, nitori wọn woye pe ibaṣepọ wọn pẹlu rẹ ko mu ikankan wa fun wọn ju idamu lọ.
Sibẹsibẹ bibeli sọ pe Dafidi ko ba ọkan jẹ nitori awọn nkan wọnyi. Dipo eyi, o fun ara rẹ ni okun ninu Oluwa, niwọn igba ti O mọ pe o di dandan ki O fun oun ni iṣẹgun ni gbogbo ọna, ki O si tun fi opin si gbogbo awọn ọjọ irinkinri rẹ ni ọjọ kan (1Samuẹli 30:6). Idi ni yi ti o ṣe sọ pe oun ni igbagbọ pe oun yoo ri didara Oluwa ni ilẹ alaye. Ṣe o wa ri tabi ko ri? O ri. O ri didara Ọlọrun ni oju ẹmi rẹ, ko si ki i ṣe lẹyin iku rẹ. Ko kan di ọba lori orilẹ-ede Isiraẹli nikan, o tun ni oore-ọfẹ ti ko wọpọ lati fi ọkan lara awọn ọmọkunrin rẹ jọba lori ilẹ na ki o to ku.
Ṣugbọn ki lo fa ti Dafidi fi ri didara Oluwa nikẹyinkẹyin ni oju ẹmi rẹ, pẹlu gbogbo iriri buruku ti o ni gẹgẹ bi ọdọmọkunrin? Bi a ti ṣe ri ninu ẹsẹ bibeli ti o wa loke yi, nitoripe o duro de Oluwa dipo ki o sọ ireti nu ni. Oluwa ti yan gẹgẹ bi ọba dipo Sọọlu; O si tun fun ni ọpọlọpọ ileri ti o ga, ti o si tun dara. Ṣugbọn ki o to le ri imuṣẹ awọn nkan wọnyi, o nilo lati fi igbagbọ ati suuru rẹ ninu Oluwa han. Lotitọ, o nilo lati ṣe eyi fun ọdun melokan. Amọ, igbagbọ rẹ ninu Ọlọrun ati suuru rẹ ko ja si pabo. Nitorina, o wa le sọ fun awọn miran ninu orin rẹ ti o wa loke pe ki awọn naa ṣe bi oun ṣe ṣe, ti wọn ba fẹ ri didara Oluwa ni ilẹ alaye.
Njẹ wọ na fẹ lati ri didara Oluwa ni oju aye rẹ bi? Njẹ iwọ na fẹ wa laye ati lalaafia nigbati Ọlọrun ba dana ṣun aṣọ ẹgan orilẹ-ede yi, ti O si tun wọ ni aṣọ ogo ati iyin? Ẹmi fẹ wa laye ati ni alaafia nigba ti eyi ba ṣẹle. Mo si tun fẹ ki idile mi wa laye ati lalaafia pẹlu nigba ti o ba ṣẹlẹ. Mo si wa ni igbagbọ bi ti Dafidi pe Oluwa ti o dara, ẹni ti o gba wa la kuro lọwọ ẹṣẹ wa, ti O si mu wa wa sinu ijọba ologo rẹ, yoo jẹ ki eyi ri bẹ. Nitorina, irufẹ nkan yowu ti mo le ri tabi gbọ, mi o ni ba ọkan jẹ tabi igbe igbagbọ mi ninu rẹ sọnu. Dipo bẹ, nṣe ni ma mu ọkan le, ti ma si tun duro de e. Bẹẹni, emi o duro de e nitoripe o n ṣe itọju me, O si tun ṣe gbọkanle. Njẹ iwọ naa yoo ha ṣe bakanna bi?
Ki o ni ọṣẹ alarinrin.
Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
J.O. Lawal | Igbe 25, 2021 | Nomba: Vol. 9, No. 51
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ titilai lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ ti o pari oṣu Igbe 2021. Adura mi ni pe ki ọkan rẹ ma fi gbogbo igba gba okun lati tẹwọgba ipe Ọlọrun lori aye rẹ, ki o si tun mu ni pataki, ki aye rẹ ba le ma fi gbogbo igba fi ẹwa rẹ han siwaju ati siwaju si ni eyi ti o ku ni ọjọ aye rẹ. Amin.
Bi a ṣe ri ninu bibeli, ko ki i ṣe awọn ti a mọ bi adari ijọ nikan ni Ọlọrun pe. Dipo eyi, ẹnikọọkan ti o jẹ onigbagbọ ninu Kirisiti Jesu ni O pe. Ki wa gan ni a pe wa si? … Tẹle atọka lati ka si’waju.
ỌJỌRU 26, EBIBI 2021 | AYỌKA: EFESU 4:11-16
AKỌSORI: “Awọn agba Juda si kọle, wọn si ṣe aṣeyọri nipa iyanju Hagai wolii ati Sakaria ọmọ Iddo…” (Ẹsira 6:14)
ỌRỌ AKỌSỌ
Ki ni iyatọ ti o wa laarin awọn ọmọ Isiraẹli ti Mose ko jade kuro ni Ijibiti ati awọn ọmọ wọn ti Joṣua ko wọ ilẹ Kenani? Ki lo fa ti awọn ti Mose ko jade kuro ni Ijibiti ko ṣe wọ ile ileri, ti wọn kan ranmu ninu aginju fun ogoji ọdun titi gbogbo wọn fi ṣegbe sibẹ, ṣugbọn ti awọn ọmọ wọn fi wọ ile ileri, ti wọn si ja ajaṣẹgun lori gbogbo awọn ọta wọn lati gba ilẹ na? Ṣe Ọlọrun fẹran awọn ọmọ wọn ju wọn lọ ni? Rara o! Ọlọrun ko fẹran awọn ọmọ wọn ju wọn lọ. Abi ṣe iṣedari Mose ni ko munadoko to lati ṣe itọni awọn eniyan wọnyi de ilẹ ti Ọlọrun ṣe ileri fun wọn ni? Rara o! Iṣedari Mose munadoko gigididi. Bi a tilẹ ṣe ri gan ninu bibeli, nitori pe iṣedari rẹ munadoko ni Ọlọrun ko ṣe pa gbogbo wọn run tọmọtọmọ. (Ẹkisodu 32)
Ki wa ni iṣoro gan an? Iṣoro na ni pe iha ti awọn wọnyi ko si iṣedari Mose ko bojumu to. Awọn wọnyi ko rẹ ara wọn silẹ lati ṣe amulo to peye iṣedari ati iwaasu ojiṣẹ Ọlọrun yi lati di irufẹ eniyan ti Ọlọrun fẹ ki wọn da ati lati jogun ini ti O ti ṣeleri fun awọn baba nla wọn. Dipo eyi, nṣe ni wọn fi aye gba ọtẹ, orikunkun, ikunsinu, iṣekuṣe ati bẹẹbẹẹlẹ lọ ni aye wọn ati ni aarin wọn. A tilẹ ri igba ti wọn fi ara wọn jin fun ibọriṣa, nitoripe Mose kan fi wọn silẹ fun ogoji ọjọ ati ogoji oru. Bẹẹ si ni a ri igba ti wọn pinu lati yan adari miran fun ara wọn, eyi ti yo mu wọn pada lọ si ijibiti. Ki si ni idi? Idi ni pe wọn ko fẹ nkan ti Ọlọrun fẹ fun wọn. Nigbati Mose funrarẹ yoo sọrọ nipa wọn, o sọ wipe, “Ẹyin ti n ṣọtẹ si Oluwa lati ọjọ ti mo ti mọ yin.” (Ditaronomi 9:24) Eyi fi ye wa pe Mose kọ ni iṣoro wọn. Aigbagbọ ninu Ọlọrun gan ni iṣoro wọn. Aigbagbọ wọn ni ko jẹ ki wọn gbọran si Mose lẹnu bi o ṣe yẹ. Aigbagbọ wọn ni ko jẹ ki wọn fi ilẹ ileri ṣe ifajẹ. (Wo: 1Korinnti 10:1-11; Heberu 3:19)
Ṣugbọn awọn ọmọ awọn ara Isiraẹli yi ti Joṣua ṣe idari yatọ gedegede si wọn. Awọn ko fi igba kankan ba jiyan tabi ba lagidi. Ohunkohun ti o ba si ni ki wọn ṣe, ni ibamu pẹlu aṣẹ Ọlọrun, ni wọn n ṣe. Nitorina, wọrọwọ bayi ni wọn wọ ilẹ ileri ti wọn si gba, bi o tilẹ jẹ pe wọn ba ọpọlọpọ idojukọ pade, ti wọn si tun ja ọpọlọpọ ogun. Eyi si jẹ ki o ye wa pe iha ti a ba kọ si iṣedari ti Ọlọrun ba yan fun wa ni ipa to ga lati ko ninu boya a o di irufẹ ẹni ti Ọlọrun fẹ ka da, ki a si fi ijọba rẹ ṣe erejẹ, tabi bẹẹkọ. O wa yẹ ki a ma a bere lọwọ ara wa lati mọ boya irufẹ ijọ ti Mose ko jade ni Ijibiti ni wa ni tabi irufẹ ijọ ti Joṣua ko wọ ilẹ ileri.
ṢIṢE AMULO TO PEYE IṢEDARI IJỌ ỌLỌRUN
Ki a ma deena pẹnu, ti awa na ko ba fẹ dabi ijọ ti Mose ko jade ni Ijibiti ti o kuna lati da irufẹ eniyan ti Ọlọrun fẹ ki wọn jẹ ati lati wọ ilẹ ileri, awa na gbọdọ kọ iha ti o tọ, ti o si nitunmọ si iṣedari ti O gbe kalẹ si aarin wa. Ki a si to le kọ iha ti o tọ si iṣedari ti O ṣe agbekalẹ rẹ, a kọkọ gbọdọ mọ idi ti O fi gbe e kalẹ. Ki lo de ti Ọlọrun, nigbati ti O ti sọ wa di atunbi ninu Jesu Kirisiti, ko kan jẹ ki ẹnikọọkan wa ma da ṣe nkan tirẹ, ki o si ma da rin irin igbagbọ rẹ? Idi ni pe O fẹ ki o ye wa pe ẹnikankan wa ko da wa; ara idile rẹ ni a jẹ. Ninu idile rẹ si ni yi, eto ati ọna ti o tọ lati ṣe ohun gbogbo wa fun ẹnikọọkan. Yatọ si eyi, ojuṣe wa fun ẹnikọọkan ti o jẹ ẹya ara idile yi lati ma a ṣe. Idi si ni yi ti O fi gbe iṣedari ti yoo mu ifẹ ati ete rẹ wọnyi wa si imuṣẹ laye wa. Iwọ na wo diẹ lara nkan ti apositeli Pọọlu sọ fun wa lori eyi:
“O si ti fi awọn kan fun ni bii apọsiteli; ati awọn miiran bii woliii ati awọn miiran bii ẹfanjẹlisiti ati awọn miiran bii oluṣọ-agutan ati olukọni; Lati pese awọn eniyan mimọ silẹ fun iṣẹ iranṣẹ, fun imudagba ijọ, ti i ṣe ara Kirisiti: Titi gbogbo wa yoo fi de iṣọkan igbagbọ ati imọ Ọmọ Ọlọrun, titi a o fi di ẹni pipe, titi a o fi de iwọn ẹkunrẹrẹ Kirisiti: Ki awa ki o ma ṣe jẹ ewe mọ, ti a n fi gbogbo afẹfẹ ẹkọ ti siwa ti sẹyin, ti a si n gba kiri nipa itanjẹ eniyan, nipa arekereke fun ọgbọnkọgbọn ati mu ni ṣina. Ṣugbọn ki a ma sọ otitọ ni ifẹ, ki a le maa dagbasoke ninu Kirisiti, ni ohun gbogbo, ẹni ti i ṣe ori ijọ: Lati ọdọ ẹni ti a ti n ṣe gbogbo ara ni ọkan pọ, ti o si n fi ara mọra, nipa gbogbo orikee ti n pese, (gẹgẹ bi olukuluku ẹya-ara ni iwọn tirẹ) o n mu ki ara naa bi si i, fun idagbasoke oun tikararẹ ninu ifẹ.” (Efesu 4:11-16)
Pẹlu akọsilẹ Pọọlu yi, ki ni a ri dimu gẹgẹ bi idi ti Ọlọrun ṣe pese awọn kan silẹ fun wa ninu ijọ rẹ gẹgẹ bi adari wa? Pataki ninu awọn nkan ti a ri dimu niyi:
– Ipese awọn ọmọ Ọlọrun fun iṣẹ iranṣẹ: Akọkọ, Ọlọrun pese wọn fun wa lati pese wa fun iṣẹ iranṣẹ. Eyi tunmọ si pe gbogbo ọmọ Ọlọrun ninu Kirisiti ni o ni iṣẹ iranṣẹ ti Ọlọrun fẹ ki o ma ṣe. Ọlọrun nikan ni O fẹ ma fi gbogbo igba lo wa; ko fẹ ki Eṣu tun ma a ri wa yalo. Ṣugbọn ti a ko ba pese wa fun awọn iṣẹ ti O fẹ ki a ṣe, a ko le ṣe wọn. Ti a ba si gbiyanju lati ṣe wọn lalai jẹ pe a ti ṣe wa yẹ, ko si ni ki a ma ba iṣẹ rẹ jẹ, bi awọn kan loni ṣe n ba iṣẹ rẹ jẹ, ti wọn si n tabuku orukọ rẹ. Ki a ba wa le ṣe wa yẹ lati ṣe awọn iṣẹ ti Ọlọrun fẹ ki a ma ṣe naa ni o ṣe fun wa ni awọn adari ijọ bi apọsiteli, wolii, oluṣọaguntan ati bẹẹbẹẹ lọ. Ṣugbọn ti a ko ba kọ iha ti o tọ si awọn wọnyi, iṣedari wọn ati iṣẹ iranṣẹ wọn laarin wa tabi lori wa ko si so eso ti Ọlọrun fẹ ki o so.
– Idari awọn ọmọ Ọlọrun sinu iṣọkan: Idi miran ti Ọlọrun tun ṣe pese awọn adari wọnyi fun wa ninu ijọ ni ki wọn ba le kọ wa, ki wọn si tun mojutowa titi gbogbo wa yoo fi wa ni isọkan ninu igbagbọ ati imọ wa ninu Kirisiti. Eyi tunmọ si pe iṣe awọn adari ijọ wa ni lati ri pe gbogbo wa ri ara wa bi ọkan ninu Jesu Kirisiti dipo ti a o fi ri ara wa bi ọta ara wa. Ikunna ọpọ wọn ni o si fa ti iyapa ati ipinya oniruuru fi wa laarin awa ọmọ Ọlọrun kaakiri agbaye loni. Ti wọn ba n ṣiṣe wọn bi iṣẹ, nṣe ni gbogbo gba yoo tẹwọgba ara wa bi ara kan ninu Jesu Kirisiti pẹlu ifẹ, bi o tilẹ jẹ pe awọn ara ọtọọtọ ni a n ba darapọ.
– Idari awọn ọmọ Ọlọrun fun idagbasoke ninu ẹmi: Lafikun, bi a ṣe ri ninu akọsilẹ Pọọlu, idi miran ti Ọlọrun fi ṣe agbekalẹ awọn adari fun wa ninu ijọ ni lati kọ wa ninu ọrọ Ọlọrun ati pẹlu iwa mimọ, daabo bo wa ati gbawa ni iyanju, ki a ba le dagba soke ninu ẹmi, ki a dabi Jesu ni gbogbo ọna, ki a si ye jẹ ope ti awọn alarekereke yoo ma ti kaakiri pẹlu oniruuru ẹkọ odi ati ẹkọ ailojutu. (Wo: Iṣe Apọsitẹli 20:28-31; 1Peteru 5:1-4) Nitorina, ti awọn adari wa ba n ṣe iṣẹ ti a fi ran wọn bi o ṣe tọ ati bi o ṣe yẹ, nṣe ni o yẹ ki gbogbo wa ma dagba soke si ni rinrin ati ni wiwu iwa bi i Jesu Kirisiti Oluwa wa.
Amọ ṣa o, bi mo ti ṣe sọ siwaju tẹlẹ, imuṣẹ ete Ọlọrun ninu aye wa ko ni i ṣe pẹlu iṣẹ ti awọn adara wa n ṣe nikan; o tun ni i ṣe pẹlu iha ti awa naa ba kọ si iṣedari wọn. Idi si ni yi ti a ṣe ni lati kọ lati inu bibeli iha ti o tọna fun wa lati kọ si iṣedari awọn adari ti Ọlọrun yan fun wa.
ỌRỌ IPARI
Ọlọrun ni ete daradara fun gbogbo awọn ọmọ rẹ, bi a ṣe ri ninu bibeli. Idi si ni yi ti O fi ma n fi wọn si abẹ itọni ati idari ti yoo jẹ ki ete naa le wa si imuṣẹ. Amọ, yatọ si ki wọn wa labẹ iṣedari ti o munadoko, iha ti awọn naa ba kọ si iṣedari ti a fi wọn si abẹ rẹ naa ni ipa ti o ga lati ko ninu boya ete Ọlọrun yoo wa si imuṣẹ lori aye wọn tabi ko ni wa si imuṣẹ.
IBEERE
– Ki ni o ri dimu ninu ẹkọ yi?
Lati ọwọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)