Ó burú jọjọ bí kò tilẹ̀ jẹ́ tuntun | J.O. Lawal
LTP-Ebibi-2022_11_3
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ebibi 2022. Mo gbadura pe ki iwọ ati ohun gbogbo ti o jẹ tirẹ ma fi gbogbo igba wa ni ipamọ kuro ninu gbogbo erongba ati akitiyan ibi awọn ọta ẹsin Kirisitiẹni, ni orukọ Jesu. Amin.
Ni aipẹ yi, igbe-rara jade lọ lati ibi gbogbo ni orilẹ-ede yi lodi si ipakupa ti a pa Debora Yakubu Samuẹli, ọmọ ile-iwe giga ti awọn olukọ kan ti o wa ni ipinlẹ Sokoto. Bi iṣẹlẹ yi ṣe wa buru jọjọ to, ti o si jẹ eyi ti a gbọdọ bu ẹnu atẹ lu pẹlu, ko jẹ tuntun tabi ajeji si aye yi. Irufẹ awọn iṣẹlẹ bẹẹ ti ṣẹlẹ sẹyinsẹyin, bi wọn si tun ti ṣe n ṣẹlẹ lọwọlọwọ yi kaakiri gbogbo agbaye, paapaa-julọ ni awọn ibi ti awọn eniyan ti ro pe ojuṣe wọn ni lati gbe Ọlọrun nija tabi lati da aabo bo iyi rẹ.
Njẹ o tilẹ mọ pe ni abẹ idari awọn alufa ijọ Katoliki mimọ ti Roomu, ni ọgọọgọrun ọdun sẹyin, ọpọlọpọ awọn eniyan rere ati olododo eniyan ni a sọ ni okuta pa, ti a ge lori tabi ti a dana sun laitọ nitori isọrọ-odi tabi isọkusọ? Nitorina, ti ijọ ko ba pa awọn ọmọ rẹ mọ loni, ko ki i ṣe nitoripe ko lailai ṣe bẹẹ ri; dipo eyi, o je nitoripe Ẹmi Ọlọrun ti fọ ọ mọ kuro ninu aimọkanmọkan rẹ, ti O si tun ti tun un ṣe.
Siwaju si, ko yẹ ki a gbagbe pe idi ti awọn adari ẹsin Juu ti igba aye Jesu fi pa a nipa ika. Nitori isọrọ-odi ni. Awọn Juu wọnyi, bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ko fi aye gba isọrọ-odi rara-rara. Nitorina, nigba ti Jesu bẹrẹ si ni pe ara rẹ ni ọmọ Ọlọrun, wọn ṣiro ọrọ rẹ si isọrọ-odi, wọn si bẹrẹ si ni bere fun ori rẹ. Ṣugbọn awọn adari wọn ko kan dede ki i mọlẹ ni oju ọna, ki wọn si pa a, bi awọn ọgọrọ eniyan ti inu n bi yoo ti ṣe. Dipo eyi, nṣe ni wọn mu, wọn wa awọn ti yoo jẹri lodi si, wọn si wa da ẹjọ iku fun.
Ki wa lo de ti wọn ko pa Jesu fun isọrọ-odi lẹsẹkẹsẹ ti wọn ti ri mu? Akọkọ, idi ni pe wọn mọ pe ọpọ ni ilẹ naa ni o gbagbọ pe eniyan Ọlọrun tootọ ni Jesu jẹ. Nitori eyi, ti ko ba wa jẹ pe a fi idi rẹ mulẹ daju pe O ṣe nkan èèwọ̀ kan, bi ki O sọ ọrọ odi si Ọlọrun, wọn ko le nawọ gan lailai ba ibinu awọn eniyan pade. Ka tilẹ tun gbe iyẹn sẹgbẹ kan, o lodi si ofin Mose lati pa ẹnikẹni lọna yi lalai ṣe pe a kọkọ gbọ ẹjọ rẹ lọna ti o yẹ. A kọkọ gbọdọ wa o kere ju ẹlẹri meji lati jẹri lodi si. Lẹyin eyi, a gbọdọ fi aye gba oun naa funrarẹ lati wi àwíjàre. Aijẹbẹ, nṣe ni a o ma ta ẹjẹ alaiṣẹ silẹ niwaju Ọlọrun ti a ba pa a. Bẹẹ gẹgẹ si ni a ṣe ṣe si Jesu ki a to da ẹjọ iku fun un lọna aitọ. (Wo: Ditaronomi 17:2-7; Matiu 26:57-66)
Idi keji ti a ko fi pa Jesu ni ẹsẹkẹsẹ ti a mu ni pe ofin miran ti o tun ga ju ti Mose lọ wa ni ilẹ naa nigba naa, iyẹn ofin awọn ara Roomu. Ko si wa si bi wọn yoo ṣe pa gbajumọ eniyan bi ti Jesu, bi O tilẹ jẹbi ẹsun ti a fi kan an, lalai ṣe pe wọn kọkọ gbọ ẹjọ rẹ ni ibamu pẹlu ofin yi, ti wọn ko ni bọ sinu iyọnu ti awọn adari ijọba Roomu ti o wa lori wọn ba mura lati ṣe agbeyẹwo ọrọ naa. Idi niyi ti a ṣe mu Jesu lọdọ sọdọ Pọ́ntíù Pílátù, ki o ba le fi ountẹ jan ẹjọ iku ti a ti da fun un. A ko ba wi wa tu u silẹ, ti ko ba jẹ wipe Pilatu jẹ adari ojo ati kòṣekukòṣẹyẹ kan. (Wo: Johanu 18:26-19:16)
Nitorina, ko ki n ṣe nkan tuntun ni ki a pa awọn olododo laitọ labẹ afiboju ẹsin. Iru nkan wọnyi si ma n ṣaba waye nibi ti awọn adari ba ti jẹ ojo bi ti Pilatu, ti wọn si tun fẹran iyin awọn eniyan ju iyin Ọlọrun lọ. Fun apẹẹrẹ, Pọọlu gan, ni akoko kan, ko ba di ẹni ti ọgọrọ awọn Juu kan ti inu n bi ko ba faya pẹrẹpẹrẹ nitori iru ọrọ yi, ti o ba jẹ pe ọgagun awọn jagunjagun Roomu ti a fi si Jerusalẹmu ni akoko yi jẹ ojo tabi lọra lati tete da si ọrọ naa. (Wo: Iṣe Apọsiteli 21:17-23:35)
Ki ni koko ti mo fẹ mu jade lori ọrọ yi? Oun naa ni pe bi a ti ṣe n bere fun idajọ ododo fun Debora Yakubu Samuẹli ati ti a si tun n gbadura pe ki Ọlọrun tu awọn ẹbi rẹ ninu, a ko gbọdọ kuna, gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun, lati kẹkọ lati ara nkan ti o ṣẹlẹ si. Ki si ni awọn ẹkọ fun wa ninu ọrọ naa? Akọkọ ni pe a gbọdọ ma fi gbogbo igba ṣọ ara ṣe ninu ibaṣepọ wa pẹlu awọn ẹlẹsin miran, paapaa-julọ awọn ti o korira ẹsin Kirisitiẹni, ki wọn ma ba fi akoko kankan ni idi ti o daju lati sọrọ odi si wa tabi lati da wa lẹbi.
Ẹkọ keji fun wa ninu ọrọ yi ni pe nibikibi ti iṣedari ibi ti a n gbe ba ti jẹ ojo tabi alailootọ, Ọlọrun le ma le lo o lati da aabo bo wa kurọ lọwọ iwa ika. Nitorina, ti ko ba jẹ wipe a mọ daju pe Ọlọrun fẹ lo ijiya tabi iku wa nibẹ lati ṣe ara rẹ logo, a gbọdọ ṣọra ṣe ni didasi ohunkohun ti o ba ni i ṣe pẹlu ọrọ ẹsin nibẹ. Aijẹbẹ, o ṣeeṣe ki a sun ninu Kirisiti ki akoko wa to to. Njẹ ki Ọlọrun gbogbo oore-ọfẹ tẹsiwaju lati ma pa gbogbo awọn ọmọ rẹ ni orilẹ-ede yi ati ni ibi gbogbo lagbaye mọ kuro lọwọ ibi gbogbo. Amin.
Kí o ní ọ̀sẹ̀ tí ó ga.
Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
Ó burú jọjọ bí kò tilẹ̀ jẹ́ tuntun | J.O. Lawal Read More »


