ÀKỌ́RÍ: HÉBÉRÙ 9- OLÓRÍ ÀLÙFÁÀ OHUN RERE | ÀYỌKÀ: HÉBÉRÙ 9:1-28 | ỌJỌ́RÚ 29, IGBE 2026
ÀKỌ́SÓRÍ: “Nitori Kristi kò wọ̀ ibi mimọ́ ti a fi ọwọ́ ṣe lọ ti iṣe apẹrẹ ti otitọ; ṣugbọn o lọ si ọ̀run pãpã, nisisiyi lati farahan ni iwaju Ọlọrun fun wa” (Hébérù 9:24)
Ọ̀RỌ̀ ÌSÀÁJÚ
Ninu ẹkọ ti a kọ kẹyin ninu iwe Heberu, a ri wipe Ọlọrun nilo lati fa igi le majẹmu akọkọ ti O ba awọn ọmọ Isiraẹli da nitoripe awọn eniyan naa ko ṣe deede pẹlu ofin rẹ. Ara idi si niyi ti O tun ṣe fa igi le iṣẹ iranṣẹ awọn alufa iran Aaroni nitoripe majẹmu ti a fa igi le yi ni iṣẹ iranṣẹ naa ba wa. Ọlọrun ti wa ba awọn eniyan rẹ da majẹmu miran, gẹgẹ bi O ti sọtẹlẹ lati ẹnu awọn wolii rẹ igbaani. Majẹmu tuntun yi si ni i ṣe pẹlu gbigbin ifẹ ati ilana rẹ si inu ọkan awọn eniyan naa, ki wọn ba a le ma a kiyesara lati ṣe e. A wa jẹ ki o ye wa pe Jesu ni atọna majẹmu tuntun yi, bi Mose ti ṣe jẹ atọna majẹmu akọkọ ti Ọlọrun ba wọn da. Yatọ si eyi, a tun ri wipe ko ki i ṣe kiki awọn ọmọ Isiraẹli nikan ni Ọlọrun ba da majẹmu tuntun yi – gbogbo awọn ti o ba tọ ọ wa nipasẹ Jesu ni O n ba da majẹmu naa. Nitorina, bi a ko tilẹ jẹ Juu tabi ọmọ Isiraẹli, niwọn igba ti a ti tọ Ọlọrun wa nipasẹ igbagbọ ninu Jesu Kirisiti, O ti ba awa naa da majẹmu lati gbin ifẹ rẹ ati ilana rẹ sinu wa nipasẹ Ẹmi Mimọ rẹ. Idi si ni yi ti a fi le ṣe ifẹ rẹ lalai si pe a n tọ wa sọna nipa ofin Mose.
OLÓRÍ ÀLÙFÁÀ OHUN RERE
Bi a ti wa ṣe mẹnuba tẹlẹ ni ori ikẹjọ iwe Heberu yi, gẹgẹ bi awọn alufaa iran Aaroni ṣe ni awọn ọrẹ ati ẹbọ ti wọn ma n mu tọ Ọlọrun wa ni Jesu Kirisit naa, gẹgẹ bi Olori Alufaa wa, ṣe ni nkan ti Oun naa mu tọ Ọlọrun wa. Eyi ni onkọwe yi wa gbe ẹnu le ni ori ikẹsan iwe naa. O si bẹrẹ eyi nipa fifi iyatọ ti o wa laarin agọ tabi Ibi mimọ ti awọn alufaa iran Aaroni ti n ṣiṣẹ ati eyi ti Jesu ti n ṣiṣẹ han wa. Iwọ naa wo nkan ti o sọ:
“NJẸ majẹmu iṣaju papa pẹlu ní ìlana ìsin, ati ibi mimọ́ ti aiye yi. Nitoripe a pa agọ́ kan; eyi ti iṣaju ninu eyi ti ọpá fitila, ati tabili, ati akara ifihàn gbé wà, eyiti a npè ni ibi mimọ́. Ati lẹhin aṣọ ikele keji, on ni agọ́ ti a npè ni ibi mimọ julọ; Ti o ni awo turari wura, ati apoti majẹmu ti a fi wura bò yiká, ninu eyi ti ikoko wura ti o ni manna gbé wà, ati ọpá Aaroni ti o rudi, ati awọn walã majẹmu; Ati lori rẹ̀ ni awọn kerubu ogo ti o ṣijibo ìtẹ́ ãnu; eyiti a kò le sọrọ rẹ̀ nisisiyi lọkọ̃kan. Njẹ nigbati a ti ṣe ètò nkan wọnyi bayi, awọn alufa a mã lọ nigbakugba sinu agọ́ ekini, nwọn a mã ṣe iṣẹ ìsin. Ṣugbọn sinu ekeji ni olori alufa nikan imã lọ lẹ̃kanṣoṣo li ọdún, kì iṣe li aisi ẹ̀jẹ, ti on fi rubọ fun ara rẹ̀ na, ati fun ìṣina awọn enia: Ẹmí Mimọ́ ntọka eyi pé a kò ti iṣi ọ̀na ibi mimọ́ julọ silẹ niwọn igbati agọ́ ekini ba duro. Eyiti iṣe apẹrẹ fun igba isisiyi gẹgẹ bi eyiti a nmu ẹ̀bun ati ẹbọ wá, ti kò le mu olusin di pipé niti ohun ti ẹri-ọkàn, Eyiti o wà ninu ohun jijẹ ati ohun mimu ati onirũru ìwẹ, ti iṣe ìlana ti ara nikan ti a fi lelẹ titi fi di igba atunṣe.” (Hébérù 9:1-10)
Njẹ o ri bayi? Ilana isin ti Ọlọrun fun awọn ọmọ Isiraẹli nigba ti O kọkọ ba wọn da majẹmu ni eyi ti a ri ninu awọn ẹṣẹ bibeli wọnyi. Lara rẹ ni a si ti ri wipe a pin agọ ijọsin si meji, iyẹn ibi mimọ ati ibi mimọ julọ. Wayi o, oniruuru awọn alufaa ni o le wọ ibi mimọ lati jọsin niwaju Ọlọrun ni ojoojumọ. Amọ olori alufaa nikan ni o ni aṣẹ lati wọ ibi mimọ julọ. Ẹkan lọdun si ni o le wọ ibẹ pẹlu ẹjẹ fun iwẹnumọ ti ara rẹ ati ti awọn eniyan rẹ.
A wa n jẹ ki o ye wa pe niwọn igba ti agọ Ọlọrun ti a tipasẹ majẹmu akọkọ ti a ba awọn ọmọ Isiraẹli gbe kalẹ ba si wa sibẹ, ko si anfaani tabi aaye fun awọn ti o n jọsin Ọlọrun lati wọ ibi mimọ julọ. Eyi jasi pe wọn ko ni anfaani lati sunmọ Ọlọrun pẹkipẹki ninu ibaṣepọ wọn pẹlu rẹ.
Ki a si wa ma gbagbe pe onkọwe yi ti jẹ ki o ye wa tẹlẹ pe agọ ti aye yi jẹ ojiji ati ẹda agọ ti ọrun, ninu eyi ti Jesu Olori Alufaa wa ti n ṣiṣẹ. Nitorina, gbogbo awọn ẹbọ ati ọrẹ ti a n mu wa fun Ọlọrun ninu agọ yi naa ko kọja ẹda ati ojiji ojulowo ẹbọ ti a le ru ninu agọ ti ọrun. Eyi si jẹ ki o ye wa pẹ awọn ọrẹ ati ẹbọ wọnyi ko le sọ awọn olujọsin Ọlọrun di pipe ninu ọkan wọn. Iwulo wọn ko kọja nkan ti ara ti a le fojuri, fọwọkan ati fetigbọ.
Sibẹsibẹ, awọn ọrẹ, ẹbọ ati iwẹnumọ wọnyi jẹ ki awọn eniyan wa ni ipo ẹni ti o mọ tabi pe nipa ti ara niwaju Ọlọrun. Amọ ṣa o, ki eniyan kan ni ifarajọ pipe niwaju Ọlọrun nipa ti ara ko tunmọ si pe o pe niwaju rẹ ninu ọkan, ninu ẹmi ati nipa ti ara. Ibi ti iṣẹ iranṣẹ Jesu si ti wọle ni eyi. A gbe iṣẹ iranṣẹ rẹ gẹgẹ bi Olori Alufaa wa kalẹ lati sọ wa di pipe ninu ẹmi, ninu ọkan ati ninu ara wa ni. Lọna wo? Nipa fifi ẹjẹ ara rẹ rubọ ninu ojulowo agọ Ọlọrun ti o wa ni ọrun. Wo nkan ti a kọ silẹ fun wa ninu iwe yi lori eyi:
“Ṣugbọn nigbati Kristi de bi Olori Alufa awọn ohun rere ti mbọ̀, nipaṣe agọ́ ti o tobi ti o si pé ju ti iṣaju, eyiti a kò fi ọwọ́ pa, eyini ni, ti kì iṣe ti ẹ̀da yi. Bẹ̃ni kì iṣe nipasẹ ẹ̀jẹ ewurẹ ati ọmọ malu, ṣugbọn nipa ẹ̀jẹ on tikararẹ̀ o wọ ibi mimọ́ lẹ̃kanṣoṣo, lẹhin ti o ti ri idande ainipẹkun gbà fun wa. Nitori bi ẹ̀jẹ akọ malu ati ewurẹ ti a fi nwọ́n awọn ti a ti sọ di alaimọ́ ba nsọ-ni-di-mimọ́ fun iwẹnumọ ara, Melomelo li ẹ̀jẹ Kristi, ẹni nipa Ẹmí aiyeraiye ti a fi ara rẹ̀ rubọ si Ọlọrun li aini àbawọn, yio wẹ̀ ẹrí-ọkàn nyin mọ́ kuro ninu okú ẹṣẹ lati sìn Ọlọrun alãye? Ati nitori eyi li o ṣe jẹ alarina majẹmu titun pe bi ikú ti mbẹ fun idande awọn irekọja ti o ti wà labẹ majẹmu iṣaju, ki awọn ti a ti pè le ri ileri ogún ainipẹkun gbà.” (Hébérù 9:11-15)
Ki ni a ri nibiyi? Akọkọ, a ri wipe Jesu Kirisiti jẹ Olori Alufaa awọn ohun rere ti Ọlọrun ti pese silẹ fun wa. Ekeji, a ri wipe ninu agọ ti ọrun, eyi ti a ko fi ọwọ kọ ni O ti ṣe iṣẹ iranṣẹ rẹ fun wa. Ẹkẹta, a ri wipe ẹjẹ ara rẹ, dipo ẹjẹ ẹranko, ni O fi ṣe iwẹnumọ fun ẹṣẹ wa. Ẹkẹrin, a ri wipe ẹkan ṣoṣo ni O nilo lati ṣe etutu ati iwẹnumọ fun ẹṣẹ gbogbo wa, yala Juu ni wa ni tabi Keferi.
Wayi o, nipa fifi ẹjẹ ara rẹ ṣe etutu fun ẹṣẹ wa, Jesu ti gba idande ayeraye fun wa kurọ lọwọ ẹṣẹ, kuro lọwọ eṣu ati kuro lọwọ idajọ Ọlọrun. Yatọ si eyi, niwọn igba ti ẹjẹ awọn ẹranko ti a fi n ṣe etutu fun ẹṣẹ awọn eniyan labẹ majẹmu atijọ le sọ awọn olujọsin di mimọ niwaju Ọlọrun nipa ti ara, ẹjẹ Jesu lagbara lati sọ awọn ti o gbagbọ ninu rẹ di mimọ ninu ọkan wọn, ki o si fọ idibajẹ danu kuro ninu ẹri-ọkan wọn, ki wọn ba a le fi tọkan-tara si Ọlọrun ni otitọ. Ewo ni o wa san ju ninu iṣẹ ti ẹjẹ awọn maalu, aguntan ati ewuro n ṣe ati iṣẹ ti ẹjẹ Jesu, ọmọ Ọlọrun, ti O tipasẹ Ẹmi Mimọ fi ara rẹ rubọ fun wa n ṣe? Iṣẹ iranṣẹ ti ẹjẹ Jesu ni.
Siwaju si, a tun jẹ ki o ye wa pe gbogbo ẹbọ ti wọn n ru ni abẹ majẹmu iṣaju ko fun awọn ti a n titori wọn ru wọn ni idande kuro lọwọ gbese ẹṣẹ. Awọn ẹbọ wọnyi, bi a ti ṣe ri ni ori ikẹwa iwe yi, kan n da ọwọ bo ẹṣẹ awọn eniyan mọlẹ ni. Etutu ti Jesu ṣe ni o ṣẹṣẹ mojuto gbogbo awọn ẹṣẹ ti wọn ti da ni abẹ majẹmu yi. Nitorina, awọn ti o ba tọ Ọlọrun wa nipasẹ rẹ le mọ daju pe awọn yoo ri ileri ogun ainipẹkun ti Ọlọrun ṣe fun awọn eniyan gba. Awọn ti o ba wa tẹsiwaju lati ma ru ẹbọ ninu agọ ti majẹmu iṣaju wa nkọ? Ki ni wọn yoo ri gba lọwọ Ọlọrun? Wọn ko le ri nkankan gba lọwọ rẹ mọ. Nitoripe a ti pa majẹmu naa ati ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu rẹ ti.
Onkọwe yi tun wa gbiyanju lati ran awọn onkawe rẹ leti pe majẹmu akọkọ ti Ọlọrun ba awọn ọmọ Isiraẹli da jẹ majẹmu ẹjẹ. Eyi jasi pe ki majẹmu ti o nitumọ kankan to le fi idi mulẹ, iku gbọdọ waye. Idi niyi ti awọn ti o ba kọ iwe ogun wọn silẹ fi gbọdọ ku naa, ki a to le ṣiṣẹ lori iwe ogun wọn. A si ri wipe gbogbo nkan ti o ni i ṣe pẹlu majẹmu iṣaju ni a fi ẹjẹ wọn, ki majẹmu tabi imulẹ naa ati awọn ofin ti o sorọ mọ to fi ẹṣẹ mulẹ.
Bakanna ni o si ṣe ri pẹlu majẹmu tuntun ti Ọlọrun n ba awọn eniyan rẹ da nipa Jesu. A nilo lati fi idi ohun naa mulẹ pẹlu itajẹsilẹ, ki ogun ti Ọlọrun ti ṣe ileri fun awọn eniyan ba a le jẹ ti wọn. Awọn nkan wọnyi ni onkọwe yi wa kọ silẹ fun wa lati ṣe alaye lẹsẹẹsẹ pataki iku Jesu fun idande gbogbo araye. Iwọ naa wo nkan ti o kọ:
“Nitori nibiti iwe-ogún ba gbé wà, ikú ẹniti o ṣe e kò le ṣe aisi pẹlu. Nitori iwe-ogún li agbara lẹhin igbati enia ba kú: nitori kò li agbara rara nigbati ẹniti o ṣe e ba mbẹ lãye. Nitorina li a kò ṣe yà majẹmu iṣaju papa si mimọ́ laisi ẹ̀jẹ. Nitori nigbati Mose ti sọ gbogbo aṣẹ fun gbogbo awọn enia gẹgẹ bi ofin, o mu ẹ̀jẹ ọmọ malu ati ti ewurẹ, pẹlu omi, ati owu ododó, ati ewe hissopu, o si fi wọ́n ati iwe pãpã ati gbogbo enia, Wipe, Eyi li ẹ̀jẹ majẹmu ti Ọlọrun palaṣẹ fun nyin. Bẹ gẹgẹ li o si fi ẹ̀jẹ wọ́n agọ́, ati gbogbo ohun èlo ìsin. O si fẹrẹ jẹ́ ohun gbogbo li a fi ẹ̀jẹ wẹ̀nu gẹgẹ bi ofin; ati laisi itajẹsilẹ kò si idariji. Nitorina a kò le ṣai fi iwọnyi wẹ̀ awọn apẹrẹ ohun ti mbẹ lọrun mọ́; ṣugbọn o yẹ ki a fi ẹbọ ti o san ju iwọnyi lọ wẹ̀ awọn ohun ọrun pãpã mọ́. Nitori Kristi kò wọ̀ ibi mimọ́ ti a fi ọwọ́ ṣe lọ ti iṣe apẹrẹ ti otitọ; ṣugbọn o lọ si ọ̀run pãpã, nisisiyi lati farahan ni iwaju Ọlọrun fun wa: Kì si iṣe pe ki o le mã fi ara rẹ̀ rubọ nigbakugba, bi olori alufa ti ima wọ̀ inu ibi mimọ́ lọ li ọdọ̃dún ti on ti ẹ̀jẹ ti ki ṣe tirẹ̀; Bi bẹ̃kọ on kì bá ṣai mã jìya nigbakugba lati ipilẹ aiye: ṣugbọn nisisiyi li o fi ara hàn lẹ̃kanṣoṣo li opin aiye lati mu ẹ̀ṣẹ kuro nipa ẹbọ ara rẹ̀. Niwọn bi a si ti fi lelẹ fun gbogbo enia lati kú lẹ̃kanṣoṣo, ṣugbọn lẹhin eyi idajọ: Bẹ̃ni Kristi pẹlu lẹhin ti a ti fi rubọ lẹ̃kanṣoṣo lati ru ẹ̀ṣẹ ọ̀pọlọpọ, yio farahan nigbakeji laisi ẹ̀ṣẹ fun awọn ti nwo ọna rẹ̀ fun igbala. “ (Hébérù 9:16-28)
Ṣe o ri bayi? Laisi itajẹsilẹ ko si idariji tabi iwẹnumọ ẹṣẹ. Amọ bi a ti ṣe sọ tẹlẹ, ẹjẹ awọn maalu, ewurẹ, agutan tabi ẹyẹ-ile ko le wẹ ẹṣẹ ẹnikẹni danu. Ẹjẹ wọn ko peye to lati ṣe eyi. Ẹjẹ eniyan ti ko labawọn nikan ni o le ṣe eyi. Jesu Kirisiti si nikan ni ẹni naa ti ẹjẹ rẹ ko labawọn. O ti wa ku fun wa bayi lati san gbese ẹṣẹ wa. O si ṣe eyi lẹkanṣoṣo nitoripe ẹkan ṣoṣo ni a fi aaye gba ọmọniyan lati ku ati pa ipo pada. Lẹyin eyi idajọ ni o kan. Idi si ni yi ti ko fi si nkankan ti a n pe ni akudaaya tabi atunwaye. Irọ ati ẹtan Satani ni o bi awọn nkan wọnyi.
Ni kukuru, nkan ti a n sọ ni pe Jesu ti fi ara rẹ rubọ fun ẹṣẹ araye lẹkanṣoṣo. Amọ yoo tun wa pada wa o. Lati wa ṣe kini? Ṣe lati tun wa ku fun ẹṣẹ wa ni? Rara o! O ti pari iṣẹ lori ẹsẹ wa. Nitorina, nigbakugba ti O ba farahan, yoo farahan lati fun awọn mu igbala ayeraye ati ikẹyin wa fun awọn ti o gbaagbọ, ti o si n duro de e ni.
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Koko gbogbo atotonu onkọwe Heberu ni ori ikẹsan iwe naa ni ki a le ri wipe ko si idi fun wa lati ru ẹbọ kankan fun ẹṣẹ tabi igbala wa mọ. Jesu ti ru ẹbọ kan ṣoṣo ti a nilo lati ru fun wa. A ko nilo ẹbọ ewurẹ, aguntan, maalu, ẹyẹ-ile tabi ti ẹniyan-keniyan mọ. Nitorina, nṣe ni ki a kan tẹwọgba idande ayeraye ti O ti ra fun wa, ki a si bẹrẹ si ni sin Ọlọrun tọkan-tara ni ọna ti o peye, ti o si jẹ itẹwọgba, iyẹn nipa imisi ati irolagbara Ẹmi Mimọ rẹ.
ÌBÉÈRÈ
– Ọna wo ni ẹkọ yi gba fi idi rẹ mulẹ pe ko si idi fun riru ẹbọ kankan si Ọlọrun mọ fun iwẹnumọ ẹṣẹ?
Lati ọwọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2026 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)
ÀKỌ́RÍ: HÉBÉRÙ 8- MÁJẸ̀MÚ TUNTUN | ÀYỌKÀ: HÉBÉRÙ 8:1-13 | ỌJỌ́RÚ 15, IGBE 2026
ÀKỌ́SÓRÍ: “Nitori ibaṣepe majẹmu iṣaju nì kò li àbuku, njẹ a kì ba ti wá àye fun ekeji.” (Hébérù 8:7)
Ọ̀RỌ̀ ÌSÀÁJÚ
Ninu ẹkọ ti a kọ kẹyin ninu iwe Heberu, iyẹn ni ori ikeje, a mẹnuba idi melokan ti awọn Juu ti o ti da Kirisitiẹni ati awa ti ko ki i ṣe Juu ti a ti da Kirisitiẹni fi nilo Olori Alufa miran dipo awọn Olori Alufa iran Aarọni. Olori Alufa miran ti Ọlọrun si fa kalẹ fun wa ni Jesu Kirisiti Oluwa wa. A si wa ri wipe Oun gan an ni Olori Alufa ti o yẹ wa. Nitoripe ẹni mimọ, alailegan ati alailẹsẹ ni. Yatọ si iyẹn, iku ko le di iṣẹ iranṣẹ rẹ lọwọ nitoripe O wa titi lailai. Lafikun, ko ki i ṣe Alufa ti a le rọ loye nitoripe Ọlọrun ti bura pe yoo ma a jẹ Alufa titi lailai ni ipa ẹṣẹ Melkisedeki. O wa ṣe pataki ki a mu iṣẹ iranṣẹ rẹ ni pataki, ki a ba a le ṣa amulo rẹ fun igbero wa ninu irina-ajo igbagbọ wa.
MÁJẸ̀MÚ TUNTUN
Ni ori ikẹjọ ti a ti fẹ kẹkọ, wayi, onkowe Heberu tẹsiwaju lati ti tun fun wa ni oye si lori iṣẹ iranṣẹ Jesu gẹgẹ bi Olori Alufa wa ati idi ti a fi nilo lati mu ni pataki. Iwọ naa wo nkan ti o sọ:
“NJẸ pataki ninu ohun ti a nsọ li eyi: Awa ni irú Olori Alufa bẹ̃, ti o joko li ọwọ́ ọtún itẹ́ ọla nla ninu awọn ọrun: Iranṣẹ ibi mimọ́, ati ti agọ́ tõtọ, ti Oluwa pa, kì iṣe enia. Nitori a fi olukuluku olori alufa jẹ lati mã mu ẹ̀bun wá ati lati mã rubọ: nitorina olori alufa yi pẹlu kò le ṣe aini ohun ti yio fi rubọ. Nisisiyi ibaṣepe o mbẹ li aiye, on kì bá tilẹ jẹ alufa, nitori awọn ti nfi ẹbun rubọ gẹgẹ bi ofin mbẹ: Awọn ẹniti njọsìn fun apẹrẹ ati ojiji awọn ohun ọrun, bi a ti kọ́ Mose lati ọdọ Ọlọrun wá nigbati o fẹ pa agọ́: nitori o wipe, kiyesi ki o ṣe ohun gbogbo gẹgẹ bi apẹrẹ ti a fihàn ọ lori òke. Ṣugbọn nisisiyi o ti gbà iṣẹ iranṣẹ ti o ni ọlá jù, niwọn bi o ti jẹ pe alarina majẹmu ti o dara jù ni iṣe, eyiti a fi ṣe ofin lori ileri ti o sàn jù bẹ̃ lọ. Nitori ibaṣepe majẹmu iṣaju nì kò li àbuku, njẹ a kì ba ti wá àye fun ekeji.” (Hébérù 8:1-7)
Njẹ o ri bayi? A tun fun wa ni awọn alaye siwaju si lori idi ti iṣẹ iranṣẹ Jesu gẹgẹ bi Olori Alufa ti Ọlọrun yan fun wa ṣe tayọ iṣẹ iranṣẹ Aarọni gẹgẹ bi Olori Alufa. Akọkọ, a ri wipe iṣẹ iranṣẹ Jesu gẹgẹ bi Olori Alufa n waye ninu agọ Ọlọrun tootọ ti o wa ninu awọn ọrun. Ṣugbọn iṣẹ iranṣẹ Aaroni jẹ ti agọ Ọlọrun ti aye yi. Agọ ti aye yi si wa jẹ ẹda ati ojiji agọ ti ọrun. Nitorina, ko si bi iṣẹ iranṣẹ Aarọni gẹgẹ bi Olori Alufa ninu agọ ti aye yi ṣe le peye to ti iṣẹ iranṣẹ Jesu gẹgẹ bi Olori Alufa ninu agọ ti ọrun, ti o jẹ ojulowo agọ Ọlọrun.
Siwaju si, a tun ri wipe awọn alufa ti aye yi ni awọn nkan ti wọn fi n rubọ ati jọsin niwaju Ọlọrun, bi o tilẹ jẹ wipe agọ ti aye yi ni wọn ti n ṣise, agọ ti o jẹ ojiji ati ẹda ojulowo agọ Ọlọrun ti o wa ni ọrun. Nibakanna, o ṣe pataki ki Jesu naa ni nkan ti yoo fi rubọ ati jọsin niwaju Ọlọrun. Ṣugbọn onkọwe yi ko mẹnuba eyi ni ori ikẹjọ ti a n wo yi. Ni ori ikẹsan ni o ti mẹnu ba a. (Wo: Hébérù 8:11-12)
Amọ ṣa o, nkan ti o fẹ ki a mọ daju ni ori ikẹjọ yi ni pe iṣẹ iranṣẹ Jesu gẹgẹ bi Olori Alufa wa, ati awọn ti o jẹ Juu ati awọn ti ko ki i ṣe Ju, peye ju iṣẹ iranṣẹ awọn iran Aarọni gẹgẹ bi Alufa lọ. Ọna miran ti o si tun gba peye ju lọ ni pe o jẹ iṣẹ iranṣẹ ti n ṣe atọna fun majẹmu tuntun ti Ọlọrun ti ṣe ileri pe Oun yoo ba awọn ọmọ Isiraẹli da.
Ki a ma gbagbe pe Ọlọrun ba awọn ọmọ Isiraẹli da majẹmu tabi mulẹ nigba ti O kọkọ ko wọn jade kuro ni Ijibiti (Ẹ́kísódù 24:3-8). O ba wọn mulẹ lati jẹ Ọlọrun fun wọn ati lati mu wọn gẹgẹ bi eniyan rẹ. A mọ majẹmu tabi imulẹ yi ni alakalẹ ati ofin ti wọn gbọdọ pa mọ. Aijẹbẹ, wọn ko ni ri didara Ọlọrun jẹgbadun. Dipo eyi, ibinu rẹ ni yoo ma wa sori wọn. Ṣe majẹmu yi wa mu ifẹ Ọlọrun ṣiṣẹ ninu aye wọn? Rara o! Ki ni idi? Idi ni wipe awọn eniyan naa kuna, wọn ko pa aṣẹ ati ofin Ọlọrun mọ.
Niwọn igba ti majẹmu yi si ti ni abuku, Ọlọrun nilo lati gbe ti si ẹgbẹ kan, ki O si tun ba awọn eniyan rẹ da majẹmu miran ti yoo mu ifẹ rẹ ṣẹ ninu aye wọn. Ki si ni ifẹ rẹ? Oun naa ni ki wọn ma gbe igbe aye ifẹ ati ododo. Moṣe wa ni atọna majẹmu eyi ti o kuna yi. Ṣugbọn Jesu ni atọna majẹmu ti o san, ti o si yẹ lati mu ifẹ Ọlọrun ṣẹ. Wo nkan ti onkowe yi wi nipa rẹ:
“Nitoriti o ri àbuku lara wọn, o wipe, Kiyesi i, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, ti emi o bá ile Israeli ati ile Juda dá majẹmu titun. Kì iṣe gẹgẹ bi majẹmu ti mo ti bá awọn baba wọn dá, li ọjọ na ti mo fà wọn lọwọ lati mu wọn jade kuro ni ilẹ Egipti; nitoriti nwọn kò duro ninu majẹmu mi, emi kò si kà wọn si, ni Oluwa wi. Nitori eyi ni majẹmu ti emi ó ba ile Israeli da lẹhin ọjọ wọnni, li Oluwa wi; Emi ó fi ofin mi si inu wọn, emi o si kọ wọn si ọkàn wọn: emi o si mã jẹ́ Ọlọrun fun wọn, nwọn o si mã jẹ́ enia fun mi: Olukuluku kì yio si mã kọ́ ara ilu rẹ̀ ati olukuluku arakunrin rẹ̀ wipe, Mọ̀ Oluwa: nitoripe gbogbo wọn ni yio mọ̀ mi, lati kekere de àgba. Nitoripe emi o ṣãnu fun aiṣododo wọn, ati ẹ̀ṣẹ wọn ati aiṣedede wọn li emi kì yio si ranti mọ́. Li eyi ti o wipe, Majẹmu titun, o ti sọ ti iṣaju di ti lailai. Ṣugbọn eyi ti o ndi ti lailai ti o si ngbó, o mura ati di asan.” (Hébérù 8:8-13)
Ṣe o ri bayẹn? Idi ti Ọlọrun fi fa igi le majẹmu akọkọ ti o ba awọn ọmọ Isiraẹli da ni pe awọn eniyan naa ko pa aṣẹ rẹ mọ. Ṣugbọn majẹmu tuntun ti Ọlọrun pinnu lati ba wọn da yatọ patapata si ti akọkọ yi. Lọna wo? Majẹmu eyi ni ṣe pẹlu atunda ọkan awọn eniyan naa. Bẹẹni, majẹmu yi ni ṣe pẹlu ki Ọlọrun gbin ofin ati ilana rẹ sinu ọkan wọn. Nitorina, ko ni nilo lati mu ẹnikẹni ninu wọn lati ṣe ifẹ rẹ ni tipatipa. Dipo eyi, gbogbo wọn ni yoo mọ Ọlọrun funra wọn, ti yoo si wu wọn lati ṣe ifẹ rẹ.
Yatọ si eyi, majẹmu tuntun yi jẹ eyi ti yoo mu gbogbo ẹṣẹ ati aiṣedede awọn eniyan Ọlọrun kuro. Eyi n fi han wa pe, bi o tilẹ jẹ wipe oniruuru etutu ni a nṣe fun iwẹnumọ ẹṣẹ awọn eniyan wọnyi labẹ majẹmu akọkọ nipa iranlọwọ iṣẹ iranṣẹ awọn alufa iran Aarọni, awọn etutu yi ko mu ẹṣẹ wọn kuro. Awọn etutu yi kan da aṣọ bo ẹṣẹ wọn ni. Ṣugbọn imulẹ tabi majẹmu tuntun ti Ọlọrun gbe kalẹ yi wa lati yanju gbogbo ẹṣẹ wọn patapata lọna ti Ọlọrun ko fi ni ranti wọn mọ. Jesu si wa ni atọna majẹmu yi.
Niwọn igba ti eyi si ribẹ, a jẹ wipe iṣẹ iranṣẹ Jesu gẹgẹ bi Olori Alufa wa san ni gbogbo ọna ju iṣẹ iranṣẹ awọn iran Aarọni gẹgẹ bi alufa lọ. Yatọ si iyẹn, niwọn igba ti Ọlọrun, nipa Jesu, ti ba awọn eniyan yi, iyẹn awọn ọmọ Isiraẹli, da majẹmu miran, majẹmu akọkọ ti di ogbo niyẹn, ko si wulo mọ. Ohun ti o ba si ti di ogbo, ti ko wulo mọ di nkan ti a gbọdọ gbe ju sọnu, ki a si gbagbe nipa rẹ. Bi a si ṣe ri loni, majẹmu naa ati gbogbo nkan ti o ni i ṣe pẹlu rẹ ni o ti di ohun igbagbe ni orilẹ-ede Isiraẹli.
Wayi o, ko wa ki i ṣe awọn ọmọ Isiraẹli nikan ni Ọlọrun n ba da majẹmu tuntun yi. Gbogbo awọn ti o ba tọ ọ wa nipasẹ Jesu ni o le jẹ igbadun majẹmu naa. Lotitọ, Ọlọrun ko ba awọn ti ko i ṣe Juu tabi ọmọ Isiraẹli da majẹmu kankan tẹlẹ ri. Nitori naa, awọn le ma le sọ wipe Ọlọrun n ba awọn da majẹmu tuntun. Ṣugbọn wọn ṣa lẹtọ lati sọ wipe Ọlọrun ti ba awọn naa da majẹmu bayi lati sọ wọn di eniyan mimọ rẹ.
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Koko nkan ti a n sọ naa ni pe iṣẹ iranṣẹ Jesu gẹgẹ bi Olori Alufa fun wa peye ni gbogbo ọna ju iṣẹ Aaroni ati iran rẹ gẹgẹ bi Alufa fun awọn ọmọ Isiraẹli lọ. Nipa iṣẹ iranṣẹ Jesu gẹgẹ bi Olori Alufa wa yi si ni Ọlọrun ṣe ba wa da majẹmu tabi mulẹ lati tun wa da, lati gbin ifẹ rẹ si ọkan wa ati fun wa imọ otitọ nipa ara rẹ. Nitorina, a ko nilo lati joko ti ofin Mose lati ha sori, ki a to le ṣe ifẹ Ọlọrun. Idi si ni pe Ọlọrun funrarẹ ṣetan lati kọ ọkan wa ni ifẹ rẹ ati lati fun wa ni okun lati ma a fi igba gbogbo ṣe e. Ṣe eyi wa tọpẹ tabi ko tọpẹ? O tọpẹ.
ÌBÉÈRÈ
– Ṣe alaye iyatọ laarin majẹmu akọkọ ti Ọlọrun ba awọn ọmọ Isiraẹli da ati majẹmu ekeji ti O ba wọn da?
Láti ọwọ́ Johnson O. Lawal
Copyright © 2026 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)
ÀKỌ́RÍ: HÉBÉRÙ 7- OLÓRÍ ÀLÚFÀ TÍ O YẸ WÁ | ÀYỌKÀ: HÉBÉRÙ 7:1-28 | ỌJỌ́RÚ 25, ERẸ́NÀ 2026
ÀKỌ́SÓRÍ: “Nitorina o si le gba wọn là pẹlu titi de opin, ẹniti o ba tọ̀ Ọlọrun wá nipasẹ rẹ̀, nitoriti o mbẹ lãye titi lai lati mã bẹ̀bẹ fun wọn.” (Hébérù 7:25)
Ọ̀RỌ̀ ÌSÀÁJÚ
Ọkan gbogi lara awọn nkan ti onkọwe iwe Hebere fẹ ki o ye wa ni pe Jesu ni Olori Alufa wa. Niwọn igba ti O si jẹ Olori Alufa wa, a ni lati ni oye nipa iṣẹ iranṣẹ rẹ, ki a ba a le ṣe amulo rẹ. Oye ti a nilo lati ni yi si ni a bẹrẹ si ni fi fun wa lati awọn ẹsẹ ti o gbẹyin ori ikẹfa iwe naa. Bi a ti ṣe sọ ninu awọn ẹkọ ti a ti kọ sẹyin ninu iwe yi, nitori awọn Juu ti o ti da kirisitiẹni, ti ominu si n kọ nipa igbagbọ wọn ninu Jesu Kirisiti, ni a ṣe diidi kọ iwe yi. Ara nkan ti a si fẹ ki o ye wọn ni pe wọn ko nilo lati ru ẹbọ mọ tabi ṣe etutu mọ fun ẹṣẹ wọn. Idi si ni pe Jesu Kirisiti ti ru ẹbọ fun gbogbo ẹṣẹ wọn ati fun gbogbo ẹṣẹ awọn araye yoku. Eyi si ni o fa ti a n fi n tọka Jesu Kirisiti si wọn gẹgẹ bi Olori Alufa wọn. Pataki eyi le ma ye awa ti a ko bi sinu ẹsin ibọriṣa tabi ẹsin awọn Juu, ninu eyi ti ilana ti wa fun oniruru ẹbọ ati etutu fun iwẹnumọ ẹṣẹ. Ṣugbọn bi a ba ṣe n gbe awọn nkan ti a kọ silẹ ninu iwe yi lori Jesu gẹgẹ bi Olori Alufa wa yẹwo siwaju si, oye iwulo iṣẹ iransẹ rẹ yoo bẹrẹ si ni yi ye wa si.
OLÓRÍ ÀLÚFÀ TÍ O YẸ WÁ
Bawo wa ni Jesu ṣe jẹ Olori Alufa fun gbogbo awọn ti o gbagbọ, yala Juu ni wọn ti tabi keferi? Irufẹ Olori Alufa wo si ni? Bi a ti ṣe ri ninu awọn ẹkọ ti a kọ sẹyin, Ọlọrun funrarẹ ni O yan Jesu gẹgẹ bi Olori Alufa fun gbogbo awọn ti o gbagbọ ninu rẹ. O si yan an fun wọn lati mojuto ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu etutu fun ẹṣẹ wọn. Amọ iyatọ wa laarin Oun ati awọn alufa ti awọn Juu ti n ni ṣaaju ki O to bẹrẹ iṣẹ iranṣẹ tirẹ. Akọkọ lara awọn iyatọ yi ni pe Olori Alufa ni ni ipasẹ ẹnikan ti a n pe ni Melkisedeki dipo lati ipasẹ Aaroni. Ta wa ni Melkisedeki? Ki si ni pataki pe Jesu jẹ Olori Alufa lati ipasẹ rẹ? Awọn nkan wọnyi ni onkọwe iwe Heberu kọkọ mojuto ni ori ikeje iwe naa ti a n gbe yẹwọ lọwọlọwọ yi. Iwọ naa wo nkan ti o sọ:
“NITORI Melkisedeki yi, ọba Salemu, alufa Ọlọrun Ọgá-ogo, ẹniti o pade Abrahamu bi o ti npada lati ibi pipa awọn ọba bọ̀, ti o si sure fun u; Ẹniti Abrahamu si pin idamẹwa ohun gbogbo fun; li ọna ekini ni itumọ rẹ̀ ọba ododo, ati lẹhinna pẹlu ọba Salemu, ti iṣe ọba alafia; Laini baba, laini iyá, laini ìtan iran, bẹ̃ni kò ni ibẹrẹ ọjọ tabi opin ọjọ aiye; ṣugbọn a ṣe e bi Ọmọ Ọlọrun; o wà li alufa titi. Njẹ ẹ gbà a rò bi ọkunrin yi ti pọ̀ to, ẹniti Abrahamu baba nla fi idamẹwa ninu awọn aṣayan ikogun fun. Ati nitõtọ awọn ti iṣe ọmọ Lefi, ti o gbà oyè alufa, nwọn ni aṣẹ lati mã gbà idamẹwa lọwọ awọn enia gẹgẹ bi ofin, eyini ni, lọwọ awọn arakunrin wọn, bi o tilẹ ti jẹ pe, nwọn ti inu Abrahamu jade. Ṣugbọn on ẹniti a kò tilẹ pitan iran rẹ̀ lati ọdọ wọn wá, ti gbà idamẹwa lọwọ Abrahamu, o si ti sure fun ẹniti o gbà ileri. Ati li aisijiyan rara ẹniti kò to ẹni li ã sure fun lati ọdọ ẹniti o jù ni. Ati nihin, awọn ẹni kikú gbà idamẹwa; ṣugbọn nibẹ̀, ẹniti a jẹri rẹ̀ pe o mbẹ lãye. Ati bi a ti le wi, Lefi papa ti ngbà idamẹwa, ti san idamẹwa nipasẹ Abrahamu. Nitori o sá si mbẹ ni inu baba rẹ̀, nigbati Melkisedeki pade rẹ̀.” (Hébérù 7:1-10)
Ki ni a ri nipa ẹni ti a n pe ni Melkisedeki nibiyi? Akọkọ, a ri wipe orukọ rẹ tunmọ si ọba ododo. Ekeji, a pe e ni ọba Salẹmu, iyẹn ọba alaafia. Ẹkẹta a tun ri wipe alufa Ọlọrun Ọga-ogo ni. Ẹkẹrin, a ri wipe ko ni ibẹrẹ ọjọ tabi opin ọjọ, ko ni iya, ko ni baba, ko si ni itan iran. O wa jẹ alufa Ọlọrun ti O wa titi ayeraye.
Wayi o, pẹlu awọn nkan ti a sọ nipa Melkisedeki yi, dajudaju ni pe ko le e jẹ eniyan afi ifarahan Ẹmi Ọlọrun funrarẹ. A si ri wipe O farahan Aburahamu, baba nla awọn Juu, ni asiko kan ti o jagun-ṣẹgun. Aburahamu si wa fun ni idamẹwa awọn aṣayan ikogun rẹ ni asiko naa. Oun naa si bukun fun Aburahamu. Eyi jasi pe Aburahamu ri ẹni yi gẹgẹ bi ẹni ti o pọ to lati sure fun oun. Nitorina, ẹni nla, ẹni ọtọ ni Melkisedeki jẹ.
Lati wa jẹ ki oye bi Jesu ṣe to gẹgẹ bi Olori Alufa ye wa, onkọwe yi fi iyatọ han laarin Alufa Melkisedeki ati awọn alufa iran Aaroni. Lọna wo? Awọn alufa iran Aaroni a ma a ku, bi o tilẹ jẹ wipe awọn naa n gba idamẹwa lọwọ awọn eniyan wọn, iyẹn awọn ẹya Isiraẹli yoku. Ṣugbọn Melkisedeki ti o gba idamẹwa lọwọ Aburahamu ko ki i ṣe ẹni ti o le ku. Yatọ si iyẹn, a tun le sọ wipe awọn ọmọ Lefi gan ti o n gba idamẹwa lọwọ awọn eniyan wọn yoku ti kọkọ san idamẹwa fun Melkisedeki lati ipasẹ Aburahamu baba nla wọn. Nitorina, ti a ba wa sọ wipe Jesu jẹ alufa lati ipasẹ Melkisedeki, o yẹ ki awa naa le woye funrawa pe iṣẹ iranṣẹ rẹ di dandan ki o ga ju ti awọn ọmọ Lefi ati iran Aaroni lọ.
Lati wa fi idi eyi mulẹ, onkọwe iwe Heberu tẹsiwaju lati sọ eyi fun wa?
“Njẹ ibaṣepe pipé mbẹ nipa oyè alufa Lefi, (nitoripe labẹ rẹ̀ li awọn enia gbà ofin), kili o si tún kù mọ́ ti alufa miran iba fi dide nipa ẹsẹ Melkisedeki, ti a kò si wipe nipa ẹsẹ Aaroni? Nitoripe bi a ti pàrọ oyè alufa, a kò si le ṣai pàrọ ofin. Nitori ẹniti a nsọ̀rọ nkan wọnyi nipa rẹ̀ jẹ ẹ̀ya miran, lati inu eyiti ẹnikẹni koi jọsin ri nibi pẹpẹ. Nitori o han gbangba pe lati inu ẹ̀ya Juda ni Oluwa wa ti dide; nipa ẹ̀ya ti Mose kò sọ ohunkohun niti awọn alufa. O si tún han gbangba jù bẹ̃ lọ bi o ti jẹ pe alufa miran dide gẹgẹ bi Melkisedeki, Eyiti a kò fi jẹ gẹgẹ bi ofin ilana nipa ti ara, bikoṣe nipa agbara ti ìye ailopin. Nitori a jẹri pe, Iwọ ni alufa titi lai nipa ẹsẹ Melkisedeki. Nitori a mu ofin iṣaju kuro, nitori ailera ati ailere rẹ̀. (Nitori ofin kò mu ohunkohun pé), a si mu ireti ti o dara jù wá nipa eyiti awa nsunmọ Ọlọrun. Niwọn bi o si ti ṣe pe kì iṣe li aibura ni. (Nitori a ti fi wọn jẹ alufa laisi ibura, nipa ẹniti o wi fun u pe, Oluwa bura, kì yio si ronupiwada, Iwọ ni alufa kan titi lai nipa ẹsẹ Melkisedeki:) Niwọn bẹ̃ ni Jesu ti di onigbọ̀wọ́ majẹmu ti o dara jù. Ati nitõtọ awọn pupọ̀ li a ti fi jẹ alufa, nitori nwọn kò le wà titi nitori ikú: Ṣugbọn on, nitoriti o wà titi lai, o ni oyè alufa ti a kò le rọ̀ nipò. Nitorina o si le gba wọn là pẹlu titi de opin, ẹniti o ba tọ̀ Ọlọrun wá nipasẹ rẹ̀, nitoriti o mbẹ lãye titi lai lati mã bẹ̀bẹ fun wọn.“ (Hébérù 7:11-25)
Pẹlu nkan ti a ri ninu awọn ẹsẹ bibeli yi, a ri wipe ti o ba jẹ wipe iṣẹ iranṣẹ awọn alufa iran Lefi ba peye to ni, ko ni si idi fun igbedide alufa miran lati ipasẹ Melkisedeki. Ti ofin ti a tun gbe kalẹ lati ipasẹ iṣẹ iranṣẹ awọn alufa iran Aaroni ba peye to ni, a ko ni nilo lati pa a ti ṣẹgbẹ kan. Ṣugbọn nitoripe iṣẹ iranṣẹ awọn alufa iran Aaroni ati ofin ti a fi lọlẹ nipa iṣẹ iranṣẹ wọn ko peye to lati sọ awọn eniyan Ọlọrun di ẹni ti O fẹ ki wọn jẹ, Ọlọrun ni lati gbe alufa miran dide lati ipasẹ Melkisedeki dipo lati ipasẹ Aaroni tabi Lefi. Niwọn igba ti eyi si ti ri bẹ, a ni lati gbe iṣẹ iranṣẹ awọn alufa idile Aaroni ju ṣẹgbẹ kan, ki a si tun parọ ofin ti o sorọ mọ iṣẹ iranṣẹ naa. Idi ni yi ti Kirisitẹni ko ṣe nilo ofin Mose lati di ẹni itẹwọgba ati ẹni pipe niwaju Ọlọrun.
Alufa tuntun ti a wa gbe kalẹ fun wa lati mu wa pe niwaju Ọlọrun ni Jesu. A si ri wipe Jesu ko wa lati iran Lefi bikoṣe lati iran Juda. Idi ni yi ti ko fi ṣiṣẹ alufa nigba ti o wa laye tabi ki O jẹ anfaani ti awọn alufa ma n jẹ nigba ti O wa laye. Iṣẹ iranṣẹ rẹ gẹgẹ bi Olori Alufa wa jẹ eyi ti a gbe kalẹ ni ibamu pẹlu ti Melkisedeki. Yatọ si eyi, o jẹ iṣẹ iranṣẹ eyi ti a gbe kalẹ pẹlu ibura Ọlọrun pe yoo jẹ Alufa titi lailai.
Ki ni awọn nkan wọnyi n fi ye wa? Oun naa ni pe iku ko le da iṣẹ iranṣẹ Jesu duro nitori ko ki iṣe Alufa ti a yan nipa ti ara ṣugbọn eyi ti a yan nipa agbara iye anipẹkun. O tun n fi ye wa pe ko si ẹni ti o le rọpo Jesu ninu iṣẹ iranṣẹ rẹ gẹgẹ bi Alufa wa bi awọn ọmọ Aaroni ti ṣe ma n rọpo ara wọn nigba ti iku ba mu wọn lọ. Nṣe ni yoo ma jẹ Alufa wa lọ titi lailai. Nitorina o le pa gbogbo awọn ti o ba tọ Ọlọrun wa nipasẹ rẹ mọ ninu ifẹ rẹ titi de opin, nitoriti O wa laaye lati ma tọ wọn sọna ati lati ma ṣipẹ fun wọn titi lai.
Nkan ti a n jẹ ki o ye wa ni pe gbogbo wa ni a nilo alufa ti yoo ma a fi igba gbogbo ran ibaṣepọ wa pẹlu Ọlọrun lọwọ, gẹgẹ bi awọn alufa awọn Juu ṣe n ran ibaṣepọ wọn pẹlu Ọlọrun lọwọ nipa kikọ wọn ati nipa riru oniruuru ẹbọ fun wọn. Amọ awọn alufa awọn Juu ko le ran ibaṣepọ wọn pẹlu Ọlọrun lọwọ lọna ti o peye to nitoripe alailera ni awọn naa ati nitoripe iku a ma a mu wọn lọ. Idi ni yi ti Ọlọrun fi gbe Alufa miran dide ti ko ni ailera awọn eniyan, ti iku ko si tun le mu lọ, lati ran wa lọwọ ninu ibaṣepọ wa pẹlu rẹ titi a o fi wọ inu isinmi ayeraye ti O ti pese silẹ fun wa. Awa n sọ pe Jesu ni Alufa naa ti a gbe kalẹ fun wa pẹlu ibura Ọlọrun lati fi idi majẹmu miran Ọlọrun ti o peye mulẹ fun gbogbo awọn ti o ba gba a gbọ.
Eyi si ni o jẹ ki onkọwe iwe Heberu yi tẹsiwaju lati sọ eyi fun wa:
“Nitoripe irú Olori Alufa bẹ̃ li o yẹ wa, mimọ́, ailẹgan, ailẽri, ti a yà si ọ̀tọ kuro ninu ẹlẹṣẹ, ti a si gbéga jù awọn ọrun lọ; Ẹniti kò ni lati mã kọ́ rubọ lojojumọ, bi awọn olori alufa wọnni, fun ẹ̀ṣẹ ti ara rẹ̀ na, ati lẹhinna fun ti awọn enia: nitori eyi li o ti ṣe lẹ̃kanṣoṣo, nigbati o fi ara rẹ̀ rubọ. Nitoripe ofin a mã fi awọn enia ti o ni ailera jẹ olori alufa; ṣugbọn ọ̀rọ ti ibura, ti a ṣe lẹhin ofin, o fi Ọmọ jẹ, ẹniti a sọ di pipé titi lai.” (Hébérù 7:26-28)
Ṣe o ri bayẹn? Jesu gan an ni irufẹ Olori Alufa ti o yẹ wa fun ibaṣepọ ti o peye pẹlu Ọlọrun. Idi si ni pe yatọ si awọn alufa ti iran Aaroni tabi ti aye yi miran, Oun jẹ mimọ, alailegan, alaileri, alailẹṣẹ ati ẹni ti a gbega ju gbogbo ọrun ati ohun gbogbo ti Ọlọrun da lọ. Siwaju si, Jesu ko nilo lati ma fi ojoojumọ ru ẹbọ ẹṣẹ fun ara rẹ ati fun awọn ti o n tọ ọ wa bi awọn alufa iran Aaroni ati ti aye yi miran. Idi si ni pe O ti fi ara rẹ rubọ lẹkanṣoṣo fun ẹṣẹ gbogbo iran ọmọ eniyan. Nitorina, gbogbo awọn ti o ba tọ Ọlọrun wa nipasẹ rẹ le fi ọkan wọn balẹ pe awọn yoo ri aanu ati ojurere gba lati jẹ ki aye wọn lọ deede ati ni ibamu pẹlu eto ati ete Ọlọrun fun wọn.
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Wayi o, ni akotan, onkọwe iwe Heberu ṣe gbogbo atotonu yi lati jẹ ki o ye awọn Juu Kirisitẹni ti o kọkọ ka iwe naa pe wọn ko nilo iṣẹ iranṣẹ awọn alufa iran Aaroni tabi alufa ti aye yi kankan mọ lati tun ibaṣepọ wọn pẹlu Ọlọrun ṣe. Bẹẹ si ni wọn ko nilo lati ma mu ẹbọ wa fun Ọlọrun mọ bi wọn ba tilẹ dẹṣẹ tabi kuna niwaju rẹ. Idi si ni pe Jesu ti san gbogbo gbese ẹṣẹ wọn nipa fifi ara rẹ rubọ fun wọn. Oun wa ni o yẹ ki wọn tẹjumọ fun igbala wọn, fun igbero wọn, fun idariji ẹṣẹ wọn ati fun ibalẹ-ọkan wọn ninu ibaṣepọ wọn pẹlu Ọlọrun. Oun si ni o yẹ ki awa naa ti a ko ki i ṣe Juu ṣugbọn ti a ti gba a gbọ tẹjumọ fun ibaṣepọ ti o nitunmọ pẹlu Ọlọrun dipo ti a o tun fi ma lepa lati fi ara wa si abẹ ofin Mose ati iṣẹ iranṣẹ awọn alufa iran Aaroni.
ÌBÉÈRÈ
– Awọn ọna wo ni o ro wipe ẹkọ yi gba ṣe pataki fun gbogbo awọn ti o jẹ Kirisitiẹni?
– Nibo ni o woye wipe ẹkọ yi ti ba ọ wi tabi le ran ọ lọwọ gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun?
Láti ọ́wọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2026 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)
ÀKỌ́RÍ: HÉBÉRÙ 6- ÀFARAWÉ ÌGBÀGBỌ́ | ÀYỌKÀ: HÉBÉRÙ 6:1-20 | ỌJỌ́RÚ 04, ERẸ́NÀ 2026
ÀKỌ́SÓRÍ: “Ki ẹ máṣe di onilọra, ṣugbọn alafarawe awọn ti nwọn ti ipa igbagbọ́ ati sũru jogún awọn ileri.” (Hébérù 6:12)
Ọ̀RỌ̀ ÌSÀÁJÚ
Ninu awọn ẹsẹ ti o gbẹyin ori ikarun iwe Heberu, onkowe yi jẹ ki o ye wa pe nigba ti o yẹ ki awọn Kiristiẹni Juu ti o kọ lẹta yi si ti ma kọ awọn ti o ṣẹṣẹ n gbagbọ ninu Kirisiti, yala Juu tabi Keferi, nṣe ni awọn naa tun nilo ki a tun ṣẹṣẹ ma a tun wọn kọ ni awọn nkan ti a le pẹ ni ipilẹ ọrọ Ọlọrun. Ki si ni idi? Idi ni wipe ọkan wọn yigbi, ko si ṣetan lati kẹkọ. Ti ọkan wa ba yigbi, ti ko si ṣetan lati kẹkọ, a ko ni tiraka lati ṣiṣẹ tọ ohun yowu ti a ba n kọ wa, ki o ba a le ye wa. Eyi si ni ewu fun wa lọna ti o ga. O ni ewu nitoripe aimura giri tabi aiṣetan lati kọ awọn nkan ti yoo fi ẹsẹ wa mulẹ ninu ohun yowu ti a ba gbagbọ tabi ti a ba n ṣe le da wa pada sipo alainikan ṣe. Ti eyi ko ba si ni ṣẹlẹ si wa, a jẹ wipe awọn olukọ wa ko ni gba a ni aabọ lọwọ wa, ti a ba kọ lati wọn-ọn kun. Eyi ti o jasi pe awọn olukọ wa gbọdọ mura lati ti wa lati ṣiṣẹ lori awọn nkan ti wọn kọ wa, ki wọn ba a le tẹsiwaju lati bẹrẹ si ni kọ wa ni awọn nkan ti yoo jẹ ki a fi ẹsẹ mulẹ ninu otitọ ti yoo ṣe wa ni anfaani.
ÀFARAWÉ ÌGBÀGBỌ́
A si wa ri apẹrẹ eleyi ninu nkan ti onkọwe iwe Heberu gbe ẹnu le lori ni ori ikẹfa iwe naa. O n jẹ ki o ye awọn Kirisitiẹni ti o kọkọ gba lẹta yi pe o di dandan fun oun ati awọn olukọ wọn ninu ọrọ Ọlọrun yoku lati bẹrẹ si ni gbe awọn igbesẹ ti yoo jẹ ki wọn ja lẹnu ọmu, ki si wọn kọ awọn nkan ti wọn nilo lati mọ fun igbagbọ ti o ye koroo. Iwọ naa wo nkan ti o sọ lori eyi:
“NITORINA ki a fi ipilẹṣẹ ẹkọ́ Kristi silẹ, ki a lọ si pipé; li aitún fi ipilẹ ironupiwada kuro ninu okú iṣẹ lelẹ, ati ti igbagbọ́ sipa ti Ọlọrun, Ati ti ẹkọ́ ti iwẹnu, ati ti igbọwọle-ni, ati ti ajinde okú, ati ti idajọ ainipẹkun. Eyi li awa ó si ṣe, bi Ọlọrun fẹ.” (Hébérù 6:1-3)
Njẹ o ri bayẹn? Onkọwe yi n jẹ ki o ye awọn olukawe rẹ pe o di dandan fun oun lati kuro lori awọn ipilẹsẹ ẹkọ Kirisiti ati lati bẹrẹ si ni kọ wọn ni awọn ẹkọ ti yoo sọ wọn di pipe ati ẹni ti o dangajia ninu igbagbọ. Awọn ẹkọ wo ni o wa pe ni ipilẹsẹ ẹkọ Kirisiti? O pe awọn ẹkọ lori ironupiwada kuro ninu ẹsẹ, igbagbọ, iwẹnu (itẹbọmi), igbọwọle-ni, ajinde oku ati idajọ ikẹyin ni ipilẹsẹ ẹkọ Kirisiti.
Ki wa ni eyi n sọ fun wa? O n sọ fun wa pe pupọ ninu awọn nkan ti a n kọ ara wa ninu ijọ Ọlọrun loni ni ko i ti kọja ẹkọ ipilẹsẹ Kirisiti, ẹkọ fun awọn ọmọ-ọwọ ninu igbagbọ. Ti a ba tilẹ ni ki a sọ otitọ gan, ọpọ ninu awọn ti a n pe ni Kirisitiẹni loni ni oye awọn nkan ti a mẹnuba yi ko ye. Ko si ye wa nitoripe a ko ma lakaka lati ni oye wọn. Ninu ọkan wa, awọn oluṣọ-aguntan wa nikan ni o nilo lati ni oye awọn nkan wọnyi – awa ko nilo oye lori wọn. Nitorian, eyi ti ọpọ ninu wa yoo fi ma a dagba soke ninu ẹmi, ti igba aye wa yoo si ma fi ogo fun Ọlọrun, nṣe ni a duro si oju kanna.
Bi onkọwe Heberu yi si wa jẹ ki o ye wa, eyi lewu pupọ fun ọkan wa. Lọna wo? O le jẹ ki a ṣubu kuro ninu oore-ọfẹ Ọlọrun patapata. Eyi yoo si fi han pe a ko ki i ṣe ti Jesu lati ibẹrẹ pẹpẹ rara niyẹn. Wo nkan ti o sọ lori eyi:
“Nitori awọn ti a ti là loju lẹ̃kan, ti nwọn si ti tọ́ ẹ̀bùn ọ̀run wò, ti nwọn si ti di alabapin Ẹmí Mimọ́, Ti nwọn si ti tọ́ ọ̀rọ rere Ọlọrun wò, ati agbara aiye ti mbọ̀, Ti nwọn si ti ṣubu kuro, ko le ṣe iṣe lati sọ wọn di ọtun si ironupiwada, nitori nwọn tún kàn Ọmọ Ọlọrun mọ agbelebu si ara wọn li ọtun, nwọn si dojutì i ni gbangba. Nitori ilẹ ti o fi omi ojò ti nrọ̀ sori rẹ̀ nigbagbogbo mu, ti o si nhù ewebẹ ti o dara fun awọn ti a nti itori wọn ro o pẹlu, ngbà ibukún lọwọ Ọlọrun. Ṣugbọn eyiti o nhù ẹgún ati oṣuṣu, a kọ̀ ọ, kò si jìna si egún; opin eyiti yio jẹ fun ijona.” (Hébérù 6:4-8)
Ṣe o ri bayẹn? Ti a ba ti kọkọ gbagbọ ninu Jesu, ti eyi si fun wa ni anfaani lati di alabapin Ẹmi Mimọ, ti a si tun bẹrẹ si ni jẹgbadun ọrọ rere Ọlọrun ati agbara nla rẹ, ti a ba wa subu kuro ninu oore-ọfẹ yi, ko si bi a ṣe le mu wa wa si ironupiwada. Ki wa ni o le fa a ti a o fi ṣubu? Nkan ti a ti n sọrọ le lori naa ni o, ti o ni i ṣe pẹlu ki a ma ma lakaka lati mọ Jesu si ati lati ni oye ti o peye lori irufẹ ẹni ti o jẹ si wa ati ifẹ rẹ fun aye wa.
Lọna wo wa ni eyi fi le yọri si iṣubu fun wa? O le yọri si iṣubu fun wa nipa pe a n fi oore-ọfẹ Ọlọrun ṣofo. Bi a ti ṣe jẹ ki o ye wa nibiyi, ọrọ wa yoo dabi ọrọ ilẹ ti o n gba ibukun ojo ati oorun Ọlọrun si ori rẹ, ti ko si wa so eso rere fun awọn ti o n dako sori rẹ. Irufẹ ilẹ yi, bi onkọwe yi ti jẹ ki o ye wa, wa labẹ idajọ Ọlọrun. O si ṣeeṣe ki o pada dana sun un.
A si wa ri apẹrẹ irufẹ nkan wọnyi lati ara igi ọpọtọ kan ti Jesu fi re. Ki ni idi ti Jesu ṣe fi re? Idi ni pe bi o tilẹ jẹ wipe o n fun awọn eniyan ni ero pe o n ni eso lori, ko si eso kankan lori rẹ. O kan n fi oore-ọfẹ Ọlọrun ṣofo ni. (Wo: Máàkù 11:12-21)
Nibakanna, ti a ba kọ lati se amulo gbogbo oore-ọfẹ Ọlọrun ti a fi fun wa lati mọ Jesu si ati lati gbe igbe aye ti O fẹ ki a gbe, a le tipasẹ eyi ṣubu kuro ninu igbagbọ wa ninu rẹ. Ti eyi ba si lọ waye, ko ni si atunṣe mọ. A ti sọnu patapata niyẹn. Ki Ọlọrun ma jẹ ki a sọnu rara.
Idi wa niyi ti a fi nilo lati tẹsiwaju lati ma a mọ Jesu si titi ti asiko wa ni aye yi yoo fi tan. Eyi ni yoo jẹ ki a jere rẹ lẹkunrẹrẹ. Eyi ni yoo jẹ ki igbagbọ wa ninu rẹ mu wa wọ inu isinmi ayeraye Ọlọrun. A si wa le ṣe eyi nipa ṣiṣe afarawe awọn ti o fi igbagbọ wọn ninu Ọlọrun han lalai rẹwẹsi, titi wọn fi ri imuṣẹ ileri rẹ ninu aye wọn. Iwọ naa wo nkan ti a sọ ninu iwe yi lori eyi:
“Ṣugbọn, olufẹ, awa ni igbagbọ ohun ti o dara jù bẹ̃ lọ niti nyin, ati ohun ti o faramọ igbala, bi awa tilẹ nsọ bayi. Nitori Ọlọrun kì iṣe alaiṣododo ti yio fi gbagbé iṣẹ nyin ati ifẹ ti ẹnyin fihàn si orukọ rẹ̀, nipa iṣẹ iranṣẹ ti ẹ ti ṣe fun awọn enia mimọ́, ti ẹ si nṣe. Awa si fẹ ki olukuluku nyin ki o mã fi irú aisimi kanna hàn, fun ẹ̀kún ireti titi de opin: Ki ẹ máṣe di onilọra, ṣugbọn alafarawe awọn ti nwọn ti ipa igbagbọ́ ati sũru jogún awọn ileri. Nitori nigbati Ọlọrun ṣe ileri fun Abrahamu, bi kò ti ri ẹniti o pọju on lati fi bura, o fi ara rẹ̀ bura, wipe, Nitõtọ ni bibukún emi o bukún fun ọ, ati ni bibisi emi o mu ọ bisi i. Bẹna si ni, lẹhin igbati o fi sũru duro, o ri ileri na gbà. Nitori enia a mã fi ẹniti o pọjù wọn bura: ibura na a si fi opin si gbogbo ijiyan wọn fun ifẹsẹ mulẹ ọ̀rọ. Ninu eyiti bi Ọlọrun ti nfẹ gidigidi lati fi aileyipada ìmọ rẹ̀ han fun awọn ajogún ileri, o fi ibura sãrin wọn. Pe, nipa ohun aileyipada meji, ninu eyiti ko le ṣe iṣe fun Ọlọrun lati ṣeke, ki awa ti o ti sá sabẹ ãbo le ni ìṣírí ti o daju lati dì ireti ti a gbé kalẹ niwaju wa mu: Eyiti awa ni bi idakọ̀ro ọkàn, ireti ti o daju ti o si duro ṣinṣin, ti o si wọ̀ inu ile lọ lẹhin aṣọ ikele; Nibiti aṣaju wa ti wọ̀ lọ fun wa, ani Jesu, ti a fi jẹ Olori Alufa titi lai nipa ẹsẹ Melkisedeki.” (Hébérù 6:9-20)
Ki ni nkan akọkọ ti a ri ninu awọn ẹsẹ wọnyi? Oun naa ni pe ọnkọwe iwe Heberu gba wipe awọn ti o n kọ iwe yi si ko ki i ṣe awọn ti a yan fun iparun. Eyi tunmọ si pe ko ma sọ awọn nkan wọnyi lati dẹruba wọn. Dipo bẹẹ, o n sọ wọn lati pe akiyesi wọn si ewu ti o wa ninu ki wọn sọ wipe awọn gba Jesu gbọ, ki wọn si ma ma gbe igbesẹ kankan lati mọ-ọn si.
O tun wa tẹsiwaju lati jẹ ki o ye wọn pe oun mọ wipe wọn n ṣiṣẹ kakara lotitọ fun orukọ Jesu ati fun awọn eniyan rẹ. O si jẹ ki wọ mọ wipe Ọlọrun naa mọ eyi, ko si ni kuna lati san wọn ni ẹsan fun ohun gbogbo ti wọn n fi ifẹ ṣe fun awọn eniyan rẹ. Nitorina, ko fẹ ki wọn rẹwẹsi tabi ṣe ọlẹ rara ni titẹle Jesu ati ni ṣiṣẹ tọ igbagbọ wọn ninu rẹ. Dipo eyi, o fẹ ki wọn bẹrẹ si ni ṣe afarawe awọn ti o ti ipasẹ suuru ati igbagbọ di ajogun ileri Ọlọrun.
Eyi wa n pe akiyesi si nkankan, oun naa si ni pe igbagbọ ninu Jesu nikan ko to lati jẹ igbadun rẹ lẹkunrẹrẹ ati lati wọ inu isinmi Ọlọrun nipasẹ rẹ. A tun nilo suuru naa pẹlu. A si fi Aburahamu ṣe apẹrẹ fun wa ninu iwe yi. Igbagbọ nikan kọ ni o jẹ ki Aburahamu ri imuṣẹ ileri Ọlọrun fun aye rẹ. Suuru naa tun ṣiṣẹ fun imuṣẹ ileri Ọlọrun fun aye rẹ.
Onkọwe yi tun wa pe akiyesi wa si nkankan lori ileri Ọlọrun fun Aburahamu. Eyi si ni pe Ọlọrun bura ni orukọ ara rẹ fun un nigba ti O n ṣe ileri fun. Ki itumọ eyi? Itumọ rẹ ni wipe nipa bibura fun Aburahamu, Ọlọrun fẹ fi han-an dajudaju pe ileri Oun fun yoo jẹ mimuṣẹ. Bi a ti ṣe mọ tẹlẹ, Ọlọrun ko nilo lati bura fun ẹnikẹni ki ọrọ rẹ si ẹni naa to wa si imuṣẹ. Idi si ni pe Ọlọrun ko ki i parọ tabi ṣeke. Ti O ba tun wa fi ibura kun ọrọ rẹ, a jẹ wipe ko si nkan naa ti o le lailai yẹ imuṣẹ ọrọ yi niyẹn. Alabajọ ti ko si si nkankan ti o yẹ imuṣẹ ileri Ọlọrun fun Aburahamu.
Ṣugbọn ki a ma gbagbe pe ara nkan ti Ọlọrun bura lati ṣe fun Aburahamu ni pe Oun yoo bukun fun gbogbo araye nipasẹ iru ọmọ rẹ. Ta si ni iru ọmọ Aburahamu naa ti Ọlọrun sọrọ nipa? Jesu ni. Nitorina, awa ti a ba tọ Jesu wa le fọkanbalẹ pe a ko ṣe aṣiṣe rara. Idi si ni pe ireti isinmi ayeraye ti a fi fun wa ninu rẹ duro digbi bi idakọrọ ọkọ-oju omi ti a mu wọ ibi mimọ julọ Agọ Ọlọrun lati ipasẹ Jesu Kirisiti Oluwa wa, Ẹni ti O ti di Olori Alufa wa nipa ẹsẹ Melkisedeki.
Nkan ti a n sọ nipe niwọn igba ti Jesu jẹ Olori Alufa wa nipa ẹsẹ Melkisedeki, ti O si ti wọ ibi mimọ julọ Ọlọrun fun wa, a ko ni lati foya lori igbala ọkan wa. Idi ni pe iṣẹ iranṣẹ rẹ fun wa ko ni pari titi yoo fi mu gbogbo wa wọ inu isinmi Ọlọrun. Iṣẹ iranṣẹ yi ko si ni pari nitoripe Oun wa laaye titi lailai, ko ni ku rara bi awọn alufa ti aye yi ṣe ma n ku. Eyi wa yẹ ki o fun wa ni igboya ati ibalẹ-ọkan lati mu suuru ni ṣiṣe ifẹ rẹ, bi o ti wu ki idojukọ wa laye yi pọ to. Idi si nipe O wa fun wa ni gbogbo igba lati fun wa ni okun, lati ran wa lọwọ ati lati jẹ ki a ni anito oore-ọfẹ ati aanu Ọlọrun lati duro ṣinṣin ninu ifẹ rẹ titi de opin.
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Ni akotan, nkan ti onkọwe iwe Heberu n jẹ ki o ye wa ni ori ikẹfa iwe naa ni pe o ṣe pataki ki a ma a fi igba gbogbo fi suuru lakaka lati pọ si ninu imọ Jesu, lẹyin igba ti a ti gba a gbọ tan. Idi si ni pe igbagbọ ati ireti wa ninu rẹ ki i ṣe asan. Ti a ko ba wa ma a ṣe eyi, a le ṣubu kuro ninu oore-ọfẹ Ọlọrun, ki a si di ẹni egbe titi lailai.
ÌBÉÈRÈ
– Awọn ẹkọ wo ni o ri kọ ni ori ikẹfa iwa Heberu yi?
– Ki ni iwulo suuru ni riri imuṣẹ ileri Ọlọrun fun aye wa?
Lati ọwọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2026 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)
ÀKỌ́RÍ: HÉBÉRÙ 5- JÉSÙ ÀTI ÁÁRỌ́NÌ | ÀYỌKÀ: HÉBÉRÙ 5:1-14 | ỌJỌ́RÚ 11, ÈRÈLÉ 2026
ÀKỌ́SÓRÍ: “Ẹni nigba ọjọ rẹ̀ ninu ara, ti o fi ẹkún rara ati omije gbadura, ti o si bẹ̀bẹ lọdọ ẹniti o le gbà a silẹ lọwọ ikú, a si gbohun rẹ̀ nitori ẹmi ọ̀wọ rẹ̀.” (Hébérù 5:7)
Ọ̀RỌ̀ ÌSÀÁJÚ
Lati ori ikẹta iwe Heberu ni a ti bẹrẹ si ni fi Jesu han wa gẹgẹ bi Olori Alufa nla wa. Eyi ja si pe ko kan ki i ṣe Oluwa ati Olugbala wa nikan; O tun jẹ Alufa fun wa. Ki wa gan ni iṣẹ alufa? Iṣẹ alufa ni lati jẹ ki ibaṣepọ laarin eniyan ati Ọlọrun rẹ duro deede. Lati igba ti awọn eniyan ti ṣubu ninu ọgba Edeni ni ibaṣepọ wọn pẹlu ẹlẹda wọn ti mẹhẹ, ti ko si lọ deede mọ. Idi ni yi ti wọn fi nilo ẹnikan laarin wọn ti o ni oye ati imọ ifẹ Ọlọrun, ti ibaṣepọ tirẹ pẹlu Ọlọrun si duro deede lati ran wọn lọwọ ninu ibaṣepọ wọn pẹlu Ọlọrun. Ta wa ni o tọ, ti o si yẹ, ti o si tun koju osuwọn to lati ran ibaṣepọ awọn eniyan pẹlu Ọlọrun lọwọ? Ayafi ẹni ti Ọlọrun funrarẹ ba yan ni. Eniyan ko le yan ara rẹ si ipo yi. Lotitọ, ninu awọn oniruuru ẹsin ti o wa laye, awọn eniyan a ma yan ara wọn si ipo alufa. Ṣugbọn ko ki i ṣe Ọlọrun alaaye ni awọn wọnyi n ṣin bikoṣe awọn ẹmikẹmi. Bi ibaṣepọ wọn pẹlu awọn ẹmikẹmi yi ba si ṣe nipọn to naa ni wọn yoo ṣe yẹ to lati ran awọn olujọsin wọn lọwọ ni sisin awọn ẹmi buburu yi. Amọ, fun awọn ti o ba fẹ sin Ọlọrun ẹlẹda wọn, wọn ko le yan alufa fun ara wọn, bẹẹ si ni ẹnikẹni ko le yan ara rẹ le wọn lori gẹgẹ bi alufa. Ọlọrun funrarẹ ni O wa ni ipo ẹni ti O le yan alufa fun wọn.
JÉSÙ ÀTI ÁÁRỌ́NÌ
Nitorina, onkọwe iwe Heberu jẹ ki o ye wa pe idi ni yi ti o fi jẹ wipe Ọlọrun ni O yan Aarọni gẹgẹ bi olori alufa fun awọn ọmọ Isiraẹli, nigba ti O ko wọn jade kuro ni Ijibiti. Ọlọrun yan an fun wọn lati ran ibaṣepọ wọn pẹlu rẹ lọwọ. O yan an fun wọn lati ma fun wọn ni oye nkan ti o jẹ itẹwọgba niwaju Oun ati nkan ti ko jẹ itẹwọgba niwaju rẹ (Ìsíkíẹ́lì 44:23). Wo nkan ti a sọ ninu iwe yi lori ọrọ naa:
“NITORI olukuluku olori alufa ti a yàn ninu awọn enia, li a fi jẹ fun awọn enia niti ohun ti iṣe ti Ọlọrun, ki o le mã mu ẹ̀bun wá ati lati ṣe ẹbọ nitori ẹ̀ṣẹ: Ẹniti o le bá awọn alaimoye ati awọn ti o ti yapa kẹdun, nitori a fi ailera yi on na ká pẹlu. Nitori idi eyi li o si ṣe yẹ, bi o ti nṣe ẹbọ nitori ẹ̀ṣẹ fun awọn enia, bẹ̃ pẹlu ni ki o ṣe fun ara rẹ̀. Kò si si ẹniti o gbà ọlá yi fun ara rẹ̀, bikoṣe ẹniti a pè lati ọdọ Ọlọrun wá, gẹgẹ bi a ti pè Aaroni.” (Hébérù 5:1-4)
Ki ni nkan akọkọ ti a ri nibi nipa ẹni ti o yẹ lati duro gẹgẹ bi alufa tabi olori alufa fun awọn eniyan? Oun naa ni pe eniyan nikan naa lo le duro ni ipo alufa fun awọn eniyan ninu ibaṣepọ wọn pẹlu Ọlọrun. Nkan ekeji ti a ri nibẹ ni pe alufa gbọdọ ni nkan ti yoo ma a mu wa fun Ọlọrun lati tu u loju fun awọn eniyan. Ẹketa ni pe alufa gbọdọ jẹ eni ti o le ba awọn eniyan kẹdun nitori ailera wọn. Ara idi ti alufa fi gbọdọ jẹ eniyan niyi. Ti ko ba ki i ṣe eniyan, ko le mọ nkan ti awọn eniyan n dojukọ ninu irinajo wọn laye, awọn nkan ti o le gbe wọn kọlu Ọlọrun. Ti ko ba ki i ṣe eniyan, ko le mọ ikaarẹ awọn eniyan, iporuru ọkan wọn tabi irẹwẹsi ọkan wọn. Nitorina, ko si bi yoo ṣe le ran ibaṣepọ wọn pẹlu Ọlọrun lọwọ. Ko si si bi yoo ṣe le fi ikaanu ran wọn lọwọ lati gba idariji fun awọn irekọja wọn ati lati ronupiwada kuro ninu ẹṣẹ wọn.
Bi a si ti ṣe ri ninu awọn ẹsẹ bibeli wọnyi, eniyan ni Aaroni ti o kọkọ jẹ olori alufa akọkọ fun awọn ọmọ Isiraẹli. Nitorina, o le ba awọn ti o n ṣoju Ọlọrun fun kẹdun lori ailera ati aiṣedede wọn nitoriti oun naa ni ailera ati aiṣedede tirẹ pẹlu. A tilẹ jẹ ki o ye wa pe ara idi ni yi ti o fi ma n kọkọ ru ẹbọ fun ẹṣẹ ti ara rẹ, ki o to ru ẹbọ fun ẹṣẹ ti awọn ọmọ Isiraẹli. Irufẹ ẹni bayi ni o si le ṣiṣẹ bi o ti tọ gẹgẹ bi alufa fun awọn eniyan rẹ.
Nkan ẹkẹrin ti a ri ninu awọn ẹsẹ bibeli yi lori ọrọ alufa ni pe eniyan ko le yan ara rẹ si ipo alufa. A ti mẹnuba eleyi tẹlẹ. Ṣugbọn a tun ni lati tẹ mọ wa leti ki a ba a le mọ daju pe ko si ẹnikẹni ti o le fi ara rẹ si ipo alufa fun awọn ti o ba n sin Ọlọrun. Ọlọrun funrarẹ ni O ma n yan alufa fun awọn eniyan. Eyi si jẹ ki o ye wa pe aṣoju Ọlọrun fun awọn eniyan ni alufa n ṣe, ko ki i ṣe aṣoju awọn eniyan si Ọlọrun. Niwọn igba ti eyi si ri bẹ, ko ki i ṣe awọn eniyan ni wọn yoo ma sọ nkan ti wọn fẹ ninu ibaṣepọ wọn fun Ọlọrun; Ọlọrun ni yoo ma a sọ nkan ti O fẹ ki awọn eniyan ṣe ki ibaṣepọ rẹ pẹlu wọn ba a le lọ deede. Bẹẹ gẹgẹ ni o si ṣe ri nigba ti Ọlọrun yan Aaroni gẹgẹ bi olori alufa fun awọn ọmọ Isiraẹli.
Ṣugbọn ki a ma gbagbe pe Aaroni ko ki i ṣe alufa tabi olori alufa si gbogbo eniyan. Olori alufa si kiki awọn ọmọ Isiraẹli ni o jẹ. Awọn arọmọdọmọ rẹ naa ko si ki i ṣe alufa si gbogbo eniyan; alufa si kiki awọn ọmọ Isiraẹli ni wọn jẹ. Amọ gbogbo eniyan ni o nilo alufa ninu aye wọn. Gbogbo eniyan ni o nilo ẹnikan ti yoo ran ibaṣepọ pẹlu Ọlọrun lọwọ, ki o ba a le ma a fi gbogbo igba gunrege. Niwọn igba ti o si wa jẹ pe a ko le yan alufa fun ara wa, Ọlọrun ni lati yan alufa fun wa, eyi ti yoo ran wa lọwọ lati duro ni yiyẹ ati pipe niwaju rẹ ni gbogbo igba.
Ta wa ni Ọlọrun yoo yan tabi ti yan fun wa? Jesu ni! Nkan ti a n sọ ni pe bi Ọlọrun ti ṣe yan Aaroni gẹgẹ bi olori alufa fun awọn ọmọ Isiraẹli, bẹẹ gẹgẹ ni O si tun ṣe yan Jesu gẹgẹ bi Olori alufa fun gbogbo iran eniyan. Tani o wa ga ju laarin Jesu ati Aaroni ninu ọrọ yi? Jesu ni. Jesu ni nitoripe Olori alufa ni Oun jẹ fun gbogbo iran eniyan, pẹlupẹlu awọn ọmọ Isiraẹli. Wo nkan ti a sọ ninu iwe yi lori eyi ati awọn ọna ti Jesu ṣe gba yẹ gẹgẹ bi Olori Alufa fun gbogbo awa ti a ba tọ Ọlọrun wa nipasẹ rẹ:
“Bẹ̃ni Kristi pẹlu kò si ṣe ara rẹ̀ logo lati jẹ́ Olori Alufa; bikoṣe ẹniti o wi fun u pe, Iwọ li Ọmọ mi, loni ni mo bí ọ. Bi o ti wi pẹlu nibomiran pe, Iwọ ni alufa titi lai nipa ẹsẹ Melkisedeki. Ẹni nigba ọjọ rẹ̀ ninu ara, ti o fi ẹkún rara ati omije gbadura, ti o si bẹ̀bẹ lọdọ ẹniti o le gbà a silẹ lọwọ ikú, a si gbohun rẹ̀ nitori ẹmi ọ̀wọ rẹ̀, Bi o ti jẹ Ọmọ nì, sibẹ o kọ́ igbọran nipa ohun ti o jìya; Bi a si ti sọ ọ di pipé, o wá di orisun igbala ainipẹkun fun gbogbo awọn ti o ngbọ́ tirẹ̀: Ti a yàn li Olori Alufa lati ọdọ Ọlọrun wá nipa ẹsẹ Melkisedeki.” (Hébérù 5:6-10)
Kini nkan ti a ri nibi yi? Akọkọ ni pe Jesu Kirisiti Oluwa wa kọ ni O yan ara rẹ gẹgẹ bi Olori Alufa fun wa; Ọlọrun ni O yan an. Ekeji ni pe Ọlọrun ko yan Jesu ni Olori Alufa nipa ilakalẹ ti iran Aarọni. Dipo bẹẹ, O yan ni Olori Alufa nipa ilakalẹ ẹnikan ti a n pe ni Melkisedeki. Melkisedeki yi jẹ Alufa Ọlọrun ti O farahan Aburahamu ni igba aye rẹ, ti O si sure fun un, bi a o ti ṣe ri ninu lẹta yi nigba ti o ba ya (Jẹ́nẹ́sísì 14).
Niwọn igba ti Ọlọrun ko ti wa yan Jesu ni Olori Alufa nipa ilakalẹ ti iran Aarọni, a ko le reti pe ki O ma mu irufẹ ẹbọ ati ọrẹ ti awọn alufa iran Aarọni ma n mu wa fun Ọlọrun. O nilo lati ni awọn nkan ti yoo mu wa fun Ọlọrun ni ibamu pẹlu aṣẹ Ọlọrun funrarẹ. A o si ri irufẹ nkan ti O mu wa fun Ọlọrun gẹgẹ bi ẹbọ ati ọrẹ lẹkunrẹrẹ bi a ti ṣe n tẹsiwaju ninu ẹkọ wa ninu iwe yi (Hébérù 8:3).
Nkan ẹkẹta ti a ri ninu awọn ẹsẹ bibeli yi ni pe Ọlọrun yan Jesu ni Olori Alufa titi lailai. Eyi ja si pe iku ko le di iṣẹ iranṣẹ rẹ lọwọ, nitoripe Oun wa laaye titi lailai. Nipa bayi, gbogbo igba, gbogbo asiko ni O le ran awọn ti o ba n tọ Ọlọrun wa nipasẹ rẹ lọwọ. Njẹ eyi ko wa dara bi? O ma dara pupọ!
Amọ ṣa o, nigba ti Jesu wa laye, a jẹ ki o ye wa pe bi ko tilẹ si ni ipo ẹni ti o le ma mu ẹbọ ati ọrẹ wa fun Ọlọrun bi awọn alufa idile Aarọni, O ru ẹbọ adura si Ọlọrun. Ki ni idi? Idi ni pe eniyan pọnbele ni Oun naa jẹ. Lotitọ, ọmọ Ọlọrun ni, ọmọ Ọlọrun ti a ko bi pẹlu irugbin ẹṣẹ ninu aye rẹ. Amọ ṣa o, eniyan ni O tun jẹ pẹlu. A tilẹ ti sọ fun wa siwaju ninu iwe yi pe gbogbo nkan ti a n la kọja bi eniyan ni Jesu naa la kọja. Ọna wo lo wa gba bori? Nipa gbigbadura tọkan-tọkan si Ọlọrun, pẹlu igbe rara ati omije loju nigba miran, ni O gba bori.
Ki wa lo de ti Jesu naa ṣe nilo lati gbadura si Ọlọrun? Idi ni pe Ọlọrun nikan ni O le gba ọkan rẹ la kuro ninu gbogbo idojukọ rẹ. Ọlọrun nikan ni O le gba a la kuro lọwọ iku ayeraye, eyi ti O titori rẹ ku fun ẹṣẹ wa. Ṣe Ọlọrun wa da lohun tabi ko da lohun? Ọlọrun da lohun nitoripe tọwọtọwọ ni O fi n gbadura si. Ti awa naa ba wa fẹ bori awọn idojukọ wa laye yi, a gbọdọ fi ara wa jin fun adura gbigba si Ọlọrun, gẹgẹ bi Jesu Oluwa wa ti ṣe ṣe, ti O si di orisun igbala ainipẹkun fun gbogbo eniyan.
Wayi, o ṣe pataki ki a kiyesi nkan ti a sọ nipa Jesu nibi yi. A pe ni orisun igbala ainipẹkun fun gbogbo eniyan. Eyi jasi pe ẹnikẹni ti o ba nilo igbala ayeraye gbọdọ tọ Jesu wa, ki o si gba a gbọ ni gbogbo ọna. Aijẹbẹ, o di dandan ki ẹni naa ṣegbe.
Ki onkọwe yi to wa tẹsiwaju ninu alaye ti o n ṣe lori Jesu gẹgẹ bi Olori Alufa wa ati awọn ọna ti a le gba ṣe amulo iṣẹ iranṣẹ rẹ yi fun wa lati jere igbala ayeraye, o yabara lati sọ fun awọn Kirisitiẹni Juu ti o kọkọ gba lẹta yi pe wọn ko yinwọ rara ninu ifarajin wọn lati ni imọ ati oye ifẹ Ọlọrun fun wọn nipasẹ Jesu. Iwọ naa wo nkan ti o sọ:
“Niti ẹniti awa ni ohun pupọ̀ lati sọ, ti o si ṣoro lati tumọ, nitoripe ẹ yigbì ni gbigbọ́. Nitori nigbati akokò tó ti o yẹ ki ẹ jẹ olukọ, ẹ tun wà ni ẹniti ẹnikan yio mã kọ́ ni ibẹrẹ ipilẹ awọn ọ̀rọ Ọlọrun; ẹ si di irú awọn ti kò le ṣe aini wàra, ti nwọn kò si fẹ onjẹ lile. Nitori olukuluku ẹniti nmu wàra jẹ́ alailoye ọ̀rọ ododo: nitori ọmọ-ọwọ ni. Ṣugbọn onjẹ lile ni fun awọn ti o dagba, awọn ẹni nipa ìriri, ti nwọn nlò ọgbọ́n wọn lati fi iyatọ sarin rere ati buburu.” (Hébérù 5:11-14)
Ṣe o ri bayi pe awọn apọsiteli igbaani ni ọpọlọpọ nkan lati kọ awọn eniyan wọn, paapaa julọ awọn Juu ti wọn ti da Kirisitiẹni nigbanaa? Ṣugbọn wọn ko le kọ wọn ni awọn nkan wọnyi? Ki si ni idi? Idi ni pe ọkan ọpọlọpọ awọn ti wọn fẹ kọ ko mura silẹ lati kẹkọ. Nṣe ni o da bi ẹni pe wọn n fi tipatipa mu wọn lati mọ nipa Jesu.
O si wa ṣeni laanu pe bi o ti ṣe ri fun ọpọlọpọ wa naa ni yi loni. Lotitọ, a sọ wipe a ti gba Jesu ni Oluwa ati Olugbala wa. Ṣugbọn a ko ma a lepa lati mọ ọn si, ki ibaṣepọ wa pẹlu rẹ ati Ọlọrun ki o ba a le munadoko, ki o si yọri si igbala ainipẹkun fun wa. Nṣe ni a ma n mu ọpọ wa lori-lorun lati gbadura, lati ka bibeli ati lati fi ara wa jin fun ipade awọn ọmọ Ọlọrun nibi ti a o ti le gbọ ọrọ rẹ. Bawo wa ni a ṣe fẹ fi ẹsẹ mulẹ ninu igbagbọ wa? Bawo si ni ko ṣe ni ṣoro fun eṣu lati gbe wa sanlẹ tabi gbe wa ṣubu?
Ni kukuru, onkọwe iwe Heberu yi jẹ ki o ye wa pe nigbati o ti yẹ ki awọn Kirisitiẹni Juu yi jẹ olukọ fun awọn ti o ṣẹṣẹ n gbagbọ ninu Kirisiti Jesu, awọn gan tun nilo awọn ti yoo ma tun wọn kọ ni awọn ẹkọ ipilẹ ọrọ Ọlọrun. Bẹẹni, wọn tun nilo wara, tabi ki a pe ni omi-ọyan ti awọn ọmọ-ọwọ ma n mu, dipo ounjẹ ti o le. A ko wa le sọ wipe irufẹ awọn wọnyi ni oye igbe aye ododo ti Ọlọrun fẹ ki a ma a gbe to. Awọn ti o ba n jẹ ounjẹ ẹmi ti o le nikan ni o le gbe igbe aye ododo ti O fẹ ki a ma a gbe lọna ti yoo tẹlọrun. Idi si ni pe awọn wọnyi ni wọn ti kọ bi a ṣe le lo ọrọ Ọlọrun lati mọ iyatọ laarin rere ati buburu.
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Ni akotan, nkan ti a n jẹ ki o ye wa ni ori ikarun iwe Heberu ni pe Jesu ko ki i ṣe Oluwa ati Olugbala wa nikan; Olori Alufa ni O tun jẹ fun wa pẹlu. Amọ ti oye eyi yoo ba ye wa, a gbọdọ ṣetan lati mọ-ọn siwaju si. Eyi ni yoo ran wa lọwọ lati le ṣe amulo iṣẹ iranṣẹ rẹ gẹgẹ bi Olori Alufa wa, ki a si fi ẹsẹ wa mulẹ ṣinṣin ninu igbala ainipẹkun ti O ti ra fun wa.
ÌBÉÈRÈ
– Ki ni o ro wipe o fa ti ko fi si ẹkọ pupọ loni laarin awọn ọmọ Ọlọrun lori Jesu gẹgẹ bi Olori Alufa wa, bi a ti ṣe ma n sọrọ lori rẹ gẹgẹ bi Oluwa ati Olugbala wa?
Lati ọwọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2026 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)
ÀKỌ́RÍ: HÉBÉRÙ 4- LÉPA LÁTI WỌ ÌSINMI RẸ | ÀYỌKÀ: HÉBÉRÙ 4:1-19 | ỌJỌ́RÚ 21, SẸRẸ 2026
ÀKỌ́SÓRÍ: “Nitorina ẹ jẹ ki a mura giri lati wọ̀ inu isimi na, ki ẹnikẹni ki o má ba ṣubu nipa apẹrẹ aigbagbọ́ kanna.” (Hébérù 4:11)
Ọ̀RỌ̀ ÌSÀÁJÚ
Bi a ti ṣe ri ninu ẹkọ ti a kọ ṣẹyin, idi kan pataki ti ọpọ ninu awọn ọmọ Isiraẹli ti Mose ko jade ni oko ẹru ko ṣe wọ ilẹ ileri ni aigbagbọ. Ki lo si fẹ aigbagbọ wọn? Iṣe-ọkan-le wọn ni o fa a. Pẹlu gbogbo iṣẹ iyanu ti Ọlọrun ṣe fun wọn, ti wọn si fi oju wọn ri, wọn ko si tun gbagbọ pe O le fun wọn ni ilẹ Kenani ti O ti ṣeleri fun wọn. Idi ni yi ti wọn ṣe kọ lati wọ ilẹ naa lọ lati gba a, ti wọn si tun pinnu lati pada si Ijibiti (Númérì 13&14). Eyi lo bi Ọlọrun ninu, ti O si pinnu wipe ọkankan ninu gbogbo wọn ti wọn ri awọn isẹ iyanu ti O ṣe ko ni wọ ilẹ ileri yi. A wa n jẹ ki o ye wa pe awọn nkan wọnyi ṣẹlẹ lati kọ wa pe ki awa naa ma fi aye gba aigbagbọ tabi iṣe-ọkan-le ninu irinajo wa pẹlu Kirisiti. Aijẹbẹ, awa naa le padanu isinmi ti Ọlọrun ti pese silẹ fun wa.
LÉPA LÁTI WỌ ÌSINMI RẸ̀
Irufẹ isinmi wo wa ni Ọlọrun ti ṣeto fun wa? Bi a ti ṣe ri ninu iwe Heberu yi, oniruuru isinmi ni Ọlọrun ma n fun awọn eniyan. A wa nilo lati mọ irufẹ isinmi eyi ti a pese fun wa, ki a ba a le mura giri lati wọ inu irẹ. Wo nkan ti a sọ ni ori ikẹrin iwe yi lori eyi:
“NITORINA, ẹ jẹ ki a bẹ̀ru, bi a ti fi ileri ati wọ̀ inu isimi rẹ̀ silẹ fun wa, ki ẹnikẹni ninu nyin ki o má bã dabi ẹnipe o ti kùna rẹ̀. Nitoripe a ti wasu ihinrere fun wa gẹgẹ bi fun awọn na, ṣugbọn ọ̀rọ ti nwọn gbọ́ kò ṣe wọn ni ire, nitoriti kò dàpọ mọ́ igbagbọ́ ninu awọn ti o gbọ́ ọ. Nitoripe awa ti o ti gbagbọ́ wọ̀ inu isimi gẹgẹ bi o ti wi, Bi mo ti bura ninu ibinu mi, nwọn ki yio wọ̀ inu isimi mi: bi o tilẹ ti ṣe pe a ti pari iṣẹ wọnni lati ipilẹ aiye. Nitori o ti sọ nibikan niti ọjọ keje bayi pe, Ọlọrun si simi ni ijọ keje kuro ninu iṣẹ rẹ̀ gbogbo. Ati nihinyi ẹ̀wẹ pe, Nwọn ki yio wọ̀ inu isimi mi. Nitorina bi o ti jẹ pe, o kù ki awọn kan wọ̀ inu rẹ̀, ati awọn ti a ti wasu ihinrere nã fun niṣãju kò wọ inu rẹ̀ nitori aigbọran: Ẹ̀wẹ, o yan ọjọ kan, o wi ninu Iwe Dafidi pe, Loni, lẹhin igba pipẹ bẹ̃; bi a ti wi niṣãju, Loni bi ẹnyin ba gbọ́ ohùn rẹ̀, ẹ máṣe sé ọkàn nyin le. Nitori ibaṣepe Joṣua ti fun wọn ni isimi, on kì ba ti sọrọ nipa ọjọ miran lẹhinna. Nitorina isimi kan kù fun awọn enia Ọlọrun. Nitoripe ẹniti o ba bọ́ sinu isimi rẹ̀, on pẹlu simi kuro ninu iṣẹ tirẹ̀, gẹgẹ bi Ọlọrun ti simi kuro ni tirẹ̀. Nitorina ẹ jẹ ki a mura giri lati wọ̀ inu isimi na, ki ẹnikẹni ki o má ba ṣubu nipa apẹrẹ aigbagbọ́ kanna. Nitori ọ̀rọ Ọlọrun yè, o si li agbara, o si mú jù idàkídà oloju meji lọ, o si ngúnni ani tìti de pipín ọkàn ati ẹmí niya, ati oríke ati ọrá inu egungun, on si ni olumọ̀ erò inu ati ète ọkàn. Kò si si ẹda kan ti kò farahan niwaju rẹ̀, ṣugbọn ohun gbogbo ni o wà nihoho ti a si ṣipaya fun oju rẹ̀ ẹniti awa ni iba lo.” (Hébérù 4:1-13)
Ki ni nkan akọkọ ti a jẹ ki o ye wa nibiyi? Ohun naa ni pe ki a ṣọ ara wa ki a ma ba kuna isinmi Ọlọrun. Idi si ni pe bi a ti ṣe waasu iyinrere si awọn ọmọ Isiraẹli ti a mu jade kuro ni Ijibiti naa ni a ti ṣe waasu iyinrere si awa naa. Lotitọ iyatọ wa laarin iwaasu ti a wa si wọn ati iwaasu ti a wa si awa. Iyinrere ti a mu tọ wọn wa ni i ṣe pẹlu bi wọn yoo ṣe kuro ni oko ẹru lati wọ inu isinmi ilẹ Kenani lọ. Ṣugbọn iyinrere ti a mu tọ awa wa ni i ṣe pẹlu bi a o ti ṣe kuro ninu ijọba okunkun lati wọ isinmi ijọba ayeraye Ọlọrun.
Ṣe iyinrere ti awọn ọmọ Isiraẹli yi gbọ wa ṣe wọn ni anfaani bi? Rara o! Ko ṣe wọn ni anfaani. Ko ṣe wọn ni anfaani nitoripe wọn ko fi tọkan-tọkan gbagbọ ninu iyinrere yi. Eyi jasi pe ọrọ Ọlọrun ti a ko ba fi tọkan-tọkan tẹwọgba ko le ṣe aye wa ni anfaani. Nitorina, ti iyinrere ti a gbọ yoo ba ṣe iṣẹ ti o yẹ ki o ṣe ninu aye wa, a gbọdọ fi tọkan-tọkan tẹwọgba. Eyi ni yoo jẹ ki a le bọ sinu isinmi ti Ọlọrun ti ṣeto fun wa.
A wa n bere pe irufẹ isinmi wo ni Ọlọrun ti ṣeto fun wa? Isinmi ayeraye ni! Amọ ṣa o, bi mo ti ṣe sọ tẹlẹ, oniruuru isinmi ni Ọlọrun ma n fun awọn eniyan. Fun awọn ọmọ Isiraẹli ti a mu jade kuro ni oko ẹru, wiwọ ilẹ ileri, ilẹ Kenani ni isinmi ti Ọlọrun ṣeto fun wọn. Amọ a tun wa ri wipe lẹyin igba ti wọn ti wọ ile ileri tan ni Ọlọrun tun sọrọ lati ẹnu Dafidi pe ọjọkọjọ ti wọn ba ti gbọ ohun Oun, wọn ko gbọdọ se ọkan wọn le. Aijẹbẹ, wọn yoo tun padanu isinmi ti Oun ti seto silẹ fun wọn. (Wo: Sáàmù 95:7-11)
Idi ni yi ti onkọwe yi ṣe sọ wipe ka sọ wipe Jọsua ti fun wọn ni isinmi ni, Ọlọrun ko tun ni ma sọrọ isinmi fun wọn. Ṣe Jọsua ko wa fun wọn ni isinmi ni, nigba ti o mu wọn gba ilẹ Kenani? O kuku fun wọn ni isinmi. Amọ oniruuru isinmi ni Ọlọrun ma n fun awọn eniyan. Nitorina, ti O ba n ba wa sọrọ nipa isinmi, a ni lati farabalẹ mọ irufẹ isinmi ti O n sọrọ nipa.
Fun apẹrẹ, Ọlọrun funrarẹ sinmi iṣẹ ti O ṣe ni atetekọṣe ni ọjọ keje. Ṣe eyi wa jasi pe Ọlọrun ko ṣiṣẹ mọ lati igba yi ni? Rara o! Jesu gan an sọ fun wa pe ojoojumọ ni Ọlọrun n ṣiṣẹ. Bẹẹ si ni pẹlu, awọn apọsiteli igbaani fi han wa ninu awọn lẹta wọn pe ojoojumọ ni Ọlọrun n ṣiṣẹ ninu aye awọn eniyan rẹ. Irufẹ isinmi wo wa ni Ọlọrun ni nigba ti O da aye tan? Isinmi kuro ninu iṣẹ iṣẹda ni O ni. Eyi ja si pe Ọlọrun ko ṣẹṣẹ ma tun ohun kankan da mọ laye yi. Gbogbo nkan ti O fẹ da ni O ti da. Amọ ṣa o, lẹyin eyi, O ṣiṣẹ irapada ọkan awọn eniyan. O si tun n ṣiṣẹ atunda ati atunṣe ninu aye awọn eniyan lọwọlọwọ yi. O si wa di opin aye yi ki O to wọ inu isinmi kuro ninu iṣe atunṣe ati atunda aye awọn eniyan. Igba yi ni Oun ati awọn ti O ti tun aye wọn da yoo wọ inu isinmi ayeraye rẹ. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 2:1-3; Jòhánù 5:17; Fílípì 2:13)
Yatọ si eyi, a jẹ ki o ye ninu abala iwe yi ti a n wo wipe awa ti a gbagbọ wọ inu isinmi Ọlọrun. Ti a ba ti wa wọ inu isinmi rẹ, ki wa lo de ti a tun sọ fun wa ninu abala iwe yi kanna pe ki a mura giri lati wọ inu isinmi rẹ? Njẹ eyi ko tako ara wọn bi? Rara o! Lọna wo?
Ko tako ara wọn nitoripe oniruuru isinmi ni igbagbọ wa ninu Ọlọrun le fun wa. Fun apẹẹrẹ, a ri awọn ọba ti Ọlọrun fun wọn ni isinmi kuro ninu igbogun ọta nitori igbagbọ wọn ninu rẹ. A si tun ri awọn eniyan miran ti Ọlọrun fun wọn ni isinmi kuro ninu ìṣẹ́, ipo iyagan, ègún ati iyọnu awọn ẹmi eṣu. Lafikun, awa ti a gbagbọ ninu Jesu naa ma gba isinmi kuro lọwọ agbara eṣu ati eṣẹ ati kuro labẹ idajọ Ọlọrun.
Nitorina, oniruuru isinmi ni igbagbọ ninu Ọlọrun le fun eniyan. Amọ isinmi kan wa ti o bori gbogbo isinmi. Isinmi yi ni isinmi ayeraye. Isinmi yi ni a wa n sọ fun wa pe ki a lepa lati wọ inu rẹ. Lọna wo? Nipa fifi tọkan-tọkan gba ọrọ Ọlọrun ti O sọ fun wa, paapaa julọ nipa Jesu Kirisiti, gbọ. Aijẹbẹ, ọrọ naa yoo da wa lẹbi dipo ti yoo fi ṣe wa ni ire.
Ki a wa ma gbagbe pe awọn Juu ti o ti gba Jesu gbọ ni a kọkọ kọ iwe yi si. Awọn Juu wọnyi si ni awọn alufa ti wọn ma n lọ ba tẹlẹ fun iwẹnumọ eṣẹ wọn ti wọn ba ṣe aṣiṣe. Amọ nibayi ti wọn ti gba Jesu gbọ, a n jẹ ki o ye wọn pe wọn ko nilo lati lọ si ọdọ awọn alufa iran Arọni kankan mọ. Idi si ni pe Jesu ti di Olori alufa Ọlọrun fun gbogbo awọn ti o gbagbọ. Nitorina, ti ẹnikẹni ba kuna ninu awọn Juu wọnyi tabi laarin awọn Keferi ti O gba Jesu gbọ, nṣe ni ki ẹni ni sunmọ Ọlọrun fun ara rẹ nipasẹ Jesu, iyẹn ni oruko Jesu. Ẹni naa yoo si ri aanu gba.
Iwọ naa wo nkan ti a kọ silẹ lori eyi:
“Njẹ bi a ti ni Olori Alufa nla kan, ti o ti la awọn ọ̀run kọja lọ, Jesu Ọmọ Ọlọrun, ẹ jẹ ki a di ijẹwọ wa mu ṣinṣin. Nitori a kò ni olori alufa ti kò le ṣai ba ni kẹdun ninu ailera wa, ẹniti a ti danwo li ọna gbogbo gẹgẹ bi awa, ṣugbọn lailẹ̀ṣẹ. Nitorina ẹ jẹ ki a wá si ibi itẹ ore-ọfẹ pẹlu igboiya, ki a le ri ãnu gbà, ki a si ri ore-ọfẹ lati mã rànnilọwọ ni akoko ti o wọ̀. “ (Hébérù 4:14-16)
Tani a pe Jesu nibiyi? Olori Alufa nla! Eyi ja si pe yatọ si pe Jesu jẹ Oluwa ati Olugbala wa, O tun wa ni ipo ẹni ti O n ṣiṣẹ fun ibaṣepọ wa pẹlu Ọlọrun, ki ibaṣepọ naa ba ma a fi igba gbogbo wa ni deede. A si tun jẹ ki o ye wa pe Jesu yi ti la awọn ọrun kọja lọ fun wa. Yatọ si eyi, a n jẹ ki o ye wa pe Jesu ko ki i ṣe Olori Alufa ti ko ni oye ailera wa ati irufẹ awọn idanwo ti a n la a kọja. Dipo eyi, o mọ ailera gbogbo wa, o si tun mọ irufẹ idojukọ ti a n la kọja. Lọna wo? Oun naa ti la gbogbo rẹ kọja ri. A ti dan Oun na wo ri ni gbogbo ọna, bi a ti ṣe n dan awa naa wo. Sibẹsibẹ, ko dẹsẹ rara.
Nitorina, Oun nikan ni o wa ni ipo ẹni ti O le ran wa lọwọ lati bori gbogbo ẹṣẹ, ki a si ma padanu isinmi ayeraye Ọlọrun fun wa. Lafikun, nitoripe O ti ṣe etutu fun gbogbo ẹṣẹ wa, a le fi igboya sunmọ ibi itẹ oore-ọfẹ Ọlọrun lati gba anu ati oore-ọfẹ fun iranlọwọ wa ni asiko yowu ti a ba nilo rẹ. Njẹ iwọ ha nilo oore-ọfẹ Ọlọrun lati duro ṣinṣin ninu igbagbọ rẹ ninu Jesu bi? Njẹ o nilo oore-ọfẹ ati aanu lati bori awọn idanwo aye rẹ, ki O si di Jesu mu ṣinṣin gẹgẹ bi Oluwa ati Olugbala rẹ bi? Ti o ba nilo rẹ, nṣe ni ki o fi igboya sunmọ Ọlọrun, ki o si beere fun. Oun yoo si da ọ lohun, yoo si ri daju wipe o ko padanu isinmi ayeraye rẹ.
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Isinmi ayeraye Ọlọrun n duro de gbogbo awọn ti o ba gbagbọ ninu Jesu Kirisiti. Amọ, wọn gbọdọ di ohun gbogbo ti O n sọ fun wọn nipa Jesu mu ṣinṣin ati tọkan-tọkan. Aijẹbẹ, bi awọn ọmọ Isiraẹli ti Mose ko jade kuro ni Ijibiti ṣe padanu isinmi ilẹ ileri ni awọn naa yoo ṣe padanu isinmi ayeraye rẹ.
Láti ọ́wọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2026 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)
ÀKỌ́RÍ: HÉBÉRÙ 3- MA ṢÉ ỌKÀN RẸ LE | ÀYỌKÀ: HÉBÉRÙ 3:1-19 | ỌJỌ́RÚ 07, SẸRẸ 2026
ÀKỌ́SÓRÍ: “Nigbati a nwipe, Loni bi ẹnyin bá gbọ́ ohùn rẹ̀, ẹ máṣe sé ọkàn nyin le, bi igba imunibinu.” (Hébérù 3:15)
Ọ̀RỌ̀ ÌSÀÁJÚ
Ninu ẹkọ ti a kọ gbẹyin ninu iwe Heberu, a ri wipe Jesu ni Ọlọrun fa kalẹ gẹgẹ bi etutu fun ẹṣẹ wa. Nitorina, Oun ni ẹni naa ti o n sọni di mimọ. Yatọ si eyi, nitoripe Oun naa ti koju ohun yowu ti a le koju gẹgẹ bi eniyan ri, iyẹn nigba ti O wa laye, ti ko si dẹṣẹ tabi kuna rara, Oun nikan ni O ni amuyẹ to lati ran gbogbo awa ti a n dan wo lọwọ, ki a ma ba a kuna. Nitori eyi ni olukọ iwe yi ṣe wa tẹsiwaju ni ori ikẹta ti a fẹ wo ninu ẹkọ yi lati tun tẹ mọ wa leti bi o ti ṣe ṣe pataki to ki a mu Jesu ni ọkunkundun, ki a si ma fi gbogbo igba fi sinu ero wa, ki a ba a le ṣe amulo oore-ọfẹ rẹ lati gbe igbe aye ti Ọlọrun fẹ ki a gbe.
MA ṢÉ ỌKÀN RẸ LE
Wayi o, ki a ma gbagbe wipe awọn Kirisitiẹni Juu ni a kọkọ kọ iwe Heberu ti a n gbeyẹwo yi si. Nitorina, lati tun tunbọ fi pataki ki wọn ma a fi igba gbogbo gbe Jesu leke ninu ero wọn ati ninu ọkan wọn han wọn, onkọwe yi tun fi aaye diẹ silẹ ninu iwe naa lati ṣe afiwe Jesu ati Mose. Ki a si ranti pe Mose ni wolii ti o fẹrẹ ṣe pataki julọ si awọn ọmọ Isiraẹli. Idi si ni pe oun ni Ọlọrun lo lati mu wọn jade kuro ni oko ẹru Ijibiti. Yatọ si eyi, oun tun ni Ọlọrun lo lati fun wọn ni ofin ati ẹsin gẹgẹ bi orilẹ-ede. Nitorina, wọn ka ọrọ Mose si ju ọrọ wolii yowu ti o le farahan ni aarin wọn lọ. Ti ọrọ wolii kan ko ba si jọ ti Mose tabi ti o ba tako ọrọ rẹ, wọn ko ni fi oju rere wo irufẹ wolii naa.
Amọ, nigba ti awọn kan ni aarin awọn ọmọ Isiraẹli tabi Juu yii ti wa gba Jesu gbọ ni Oluwa ati Olugbala wọn, o bẹrẹ si ni nira fun wọn lati mu Jesu ni pataki ju Mose lọ. Ara idi si niyi ti wọn tun fi fẹ tẹsiwaju lati ma a tẹle ofin Mose ati awọn nkan ti o sorọ mọ ẹsin ti o fi lelẹ fun wọn. O wa ṣe pataki ki a jẹ ki o ye wọn pe Jesu ga ju Mose lọ. Nitori niwọn igba ti wọn ko ba gba pe Jesu ga ju Mose lọ, wọn ko ni ri idi lati ka ọrọ Jesu si ju ọrọ rẹ lọ. Idi eyi si ni onkọwe yi ṣe sọ awọn nkan ti o wa ni ẹsẹ wọnyi fun wọn:
“NITORINA ẹnyin ará mimọ́, alabapín ìpe ọ̀run, ẹ gbà ti Aposteli ati Olori Alufa ijẹwọ wa ro, ani Jesu; Ẹniti o ṣe olõtọ si ẹniti o yàn a, bi Mose pẹlu ti ṣe ninu gbogbo ile rẹ̀. Nitori a kà ọkunrin yi ni yiyẹ si ogo jù Mose lọ niwọn bi ẹniti o kọ́ ile ti li ọla jù ile lọ. Lati ọwọ́ enia kan li a sá ti kọ́ olukuluku ile; ṣugbọn ẹniti o kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọrun. Mose nitõtọ si ṣe olõtọ ninu gbogbo ile rẹ̀, bi iranṣẹ, fun ẹrí ohun ti a o sọ̀rọ wọn nigba ikẹhin; Ṣugbọn Kristi bi ọmọ lori ile rẹ̀; ile ẹniti awa iṣe, bi awa ba dì igbẹkẹle ati iṣogo ireti wa mu ṣinṣin titi de opin.” (Hébérù 3:1-6)
Ki ni awọn nkan miran ti onkọwe yi tun sọ nipa Jesu ninu awọn ẹsẹ wọnyi? Awọn naa ni pe Jesu ni apọsiteli ati olori alufa fun gbogbo awọn ti a ti jẹwọ rẹ ni Oluwa wa. Ki ni idi ti o ṣe pe Jesu ni awọn nkan wọnyi? O pe ni awọn nkan wọnyi lati jẹ ki awọn Kirisitiẹni Juu wọnyi mọ wipe bi Mose ti ṣe jẹ apọsiteli fun wọn, ti Aaroni naa si tun jẹ olori alufa akọkọ fun wọn, bẹẹ naa ni Jesu ṣe jẹ apọsiteli ati olori alufa fun wọn. Yoo pada sọrọ lori ọna ti Jesu gba jẹ olori alufa fun awọn ti o gbagbọ bi o ti ṣe ni tẹsiwaju ninu iwe yi. Amọ nkan akọkọ ti o fẹ ki o ye awọn Kirisitẹni Juu ti o kọkọ ni anfaani lati ka iwe yi nipe Apọsiteli naa ni Jesu jẹ fun wọn.
Amọ ṣa o, ipo Jesu gẹgẹ bi apọsiteli ti Ọlọrun ran wa ga ju ti Mose lọ. Lọna wo? O ga ju lọ nitoripe iranṣẹ lasan ni Mose jẹ ninu ile Ọlọrun. Lotitọ, Mose jẹ olotitọ si Ọlọrun ninu gbogbo iṣẹ ti Ọlọrun gbe fun ninu ile rẹ. Ọlọrun funrarẹ si gbẹri rẹ jẹ (Númérì 12:7). Amọ Jesu ko ki i ṣe iranṣẹ ninu ile Ọlọrun; ọmọ ni O jẹ ninu ile rẹ. Jesu naa si wa jẹ olotitọ si Ọlọrun ninu ohun gbogbo ti O yan an lati ṣe. Idi si niyi ti O fi tọ si ọla ati ogo ju Mose lọ.
A wa tun jẹ ki o ye wa pe gbogbo awọn ti a gbagbọ ninu Jesu gan ni ile Ọlọrun ti Jesu jẹ ọmọ le lori. Nitorina, a nilo lati di igbẹkẹle ati ireti wa ninu rẹ mu ṣinṣin de opin. Aijẹbẹ, nṣe ni a gbagbọ lasan. Nitori eyi, a nilo lati kiyesi ohun yowu ti O ba n sọ fun wa nipasẹ Ẹmi rẹ ni awọn ọjọ ikẹyin wọnyi, ki a si ma ṣe aya wa le. Aijẹbẹ, igbagbọ wa ninu rẹ yoo ja si asan.
Ṣe igbagbọ eniyan ninu Jesu le ja si asan? Bẹẹni! Igbagbọ ti Ọlọrun ka si igbagbọ nitootọ ni eyi ti eniyan ni lati ibẹrẹ de opin. Igbagbọ ti ko ba ti ba eniyan kalẹ ko ki i ṣe igbagbọ otitọ ati ododo rara. Irufẹ igbagbọ yi ko si le gbe eniyan wọ ile-ogo, iyẹn inu isinmi ayeraye ti Ọlọrun ti pese silẹ fun awọn ọmọ rẹ. Nitorina, onkọwe iwe Heberu yi pe akiyesi wa si nkan ti Ẹmi Mimọ ti sọ saaju ninu Iwe Mimọ lori ọrọ yi. Iwọ naa wo o:
“Nitorina gẹgẹbi Ẹmí Mimọ́ ti wi, Loni bi ẹnyin bá gbọ́ ohùn rẹ̀, Ẹ máṣe sé ọkàn nyin le, bi igba imunibinu, bi li ọjọ idanwò li aginjù: Nibiti awọn baba nyin dán mi wò, nipa wiwadi mi, ti nwọn si ri iṣẹ mi li ogoji ọdún. Nitorina inu mi bajẹ si iran na, mo si wipe, Nigbagbogbo ni nwọn nṣìna li ọkàn wọn; nwọn kò si mọ̀ ọ̀na mi. Bi mo ti bura ni ibinu mi, nwọn ki yio wọ̀ inu isimi mi. Ẹ kiyesara, ará, ki ọkàn buburu ti aigbagbọ́ ki o máṣe wà ninu ẹnikẹni nyin, ni lilọ kuro lọdọ Ọlọrun alãye. Ṣugbọn ẹ mã gbà ara nyin niyanju li ojojumọ́, niwọn igbati a ba npè e ni Oni, ki a má bã sé ọkàn ẹnikẹni ninu nyin le nipa ẹ̀tan ẹ̀ṣẹ. Nitori awa di alabapín pẹlu Kristi, bi awa ba dì ipilẹṣẹ igbẹkẹle wa mu ṣinṣin titi de opin; Nigbati a nwipe, Loni bi ẹnyin bá gbọ́ ohùn rẹ̀, ẹ máṣe sé ọkàn nyin le, bi igba imunibinu. Nitori awọn tani bi nyin ninu nigbati nwọn gbọ́? Ki ha iṣe gbogbo awọn ti o ti ipasẹ Mose jade lati Egipti wá? Awọn tali o si binu si fun ogoji ọdún? Ki ha iṣe si awọn ti o dẹṣẹ, okú awọn ti o sun li aginjù? Awọn tali o si bura fun pe nwọn kì yio wọ̀ inu isimi on, bikoṣe fun awọn ti kò gbọran? Awa si ri pe nwọn kò le wọ̀ inu rẹ̀ nitori aigbagbọ́.” (Hébérù 3:7-19)
Ki ni a ri ninu awọn ọrọ wọnyi? Akọkọ ni pe o ṣeeṣe ki eniyan ṣe ọkan rẹ le si nkan ti Ọlọrun n ba a sọ. A si ri apẹrẹ ninu awọn ọmọ Isiraẹli ti Mose ko jade kuro ni Ijibiti. Wọn ṣe ọkan wọn le si awọn nkan ti Ọlọrun n ba wọn sọ nigba ti a ko wọn jade kuro ni Ijibiti. Nitorina, ọpọ ninu wọn ni ko wọ Ilẹ-Ileri, ti wọn si ṣofo sinu aginju. Wọn ṣofo sinu aginju nitoripe Ọlọrun binu si wọn. Ọlọrun si binu si wọn nitori ti O ka aigbọran ati iṣe-ọkan-le wọn si aigbagbọ.
Lotitọ, pẹlu igbagbọ ni awọn ọmọ Isiraẹli yi fi jade tẹle Mose kuro ni Ijibiti. Wọn ni igbagbọ pe Ọlọrun yoo fun wọn ni ilẹ Kenani nitootọ, bi o tilẹ jẹ wipe wọn ko mọ ilẹ naa tabi de ibẹ ri. Amọ ṣa o, nigba ti o ku diẹ ki wọn wọ ilẹ naa, wọn fi aigbagbọ han, wọn si kọ lati tẹsiwaju lati wọ ilẹ naa lọ. Nitorina, Ọlọrun binu si wọn, O si bura wipe wọn ko ni wọ inu ipese isinmi rẹ fun wọn. O si ri bẹẹ gẹgẹ. Ṣe a wa ri bayi wipe igbagbọ ti ko ba bani kalẹ ko ki i ṣe igbagbọ otitọ? Irufẹ igbagbọ naa ko le gbe ni leke tabi wọ inu isinmi ti Ọlọrun ti pese silẹ fun un. (Wo: Númérì 13-14)
Lẹyin ọpọ ọdun, wayi, Ẹmi Ọlọrun tipasẹ Dafidi bẹrẹ si ni kilọ fun awọn arọmọdọmọ wọn ti o pada wọ Ilẹ-Ileri naa pe ki wọn ma ṣe ya olorikunkun bi awọn baba-nla wọn. O kilọ fun wọn pe ki wọn ma ṣe ṣe ọkan wọn le nigba yowu ti Oun ba n ba wọn sọrọ. Aijẹbẹ, awọn naa yoo padanu isinmi yowu ti o ba yẹ ki o jẹ tiwọn nipasẹ aigbọran wọn.
A wa sọ gbogbo awọn nkan wọnyi fun wa lati pe akiyesi awa naa ti a ti tọ Jesu wa, yala Juu ni wa tabi a ki i ṣe Juu, lati ma ṣe ọkan wa le si ohunkohun ti Jesu ba n ba wa sọ. Dipo eyi nṣe ni ki a ma a fi ojoojumọ gba ara wa niyanju ninu otitọ Kirisiti, niwọn igba ti oni ba ti n jẹ oni, ki itanjẹ ẹṣẹ ba a jẹ ki a ṣe ọkan wa le si Ọlọrun, ki a si yipada kuro lọdọ rẹ.
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Igbagbọ ti ko ba ni bani kalẹ ko ki i ṣe igbagbọ otitọ. Nitorina, bi ọpọlọpọ awọn ọmọ Isiraẹli ti Mose ko jade lati Ijibiti ṣe padanu Ilẹ-Ileri nitoripe wọn ko fi igbagbọ wọn sinu Ọlọrun lati ibẹrẹ de opin ni awa naa ṣe le padanu isinmi ayeraye ti Ọlọrun pese silẹ fun wa ti a ko ba fi igbagbọ wa sinu Jesu lati ibẹrẹ de opin.
ÌBÉÈRÈ
– Ki ni o ṣe pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi?
Láti ọwọ́ Johnson O. Lawal
Copyright © 2026 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)
ÀKỌ́RÍ: HÉBÉRÙ 2- A NÍLÒ ÀFỌKÀNSÍ | ÀYỌKÀ: HÉBÉRÙ 2:1-18 | ỌJỌ́RÚ 19, BELU 2025
ÀKỌ́SÓRÍ: “Nitorina o yẹ ti awa iba mã fi iyè gidigidi si ohun wọnni ti awa ti gbọ́, ki a má bã gbá wa lọ kuro ninu wọn nigbakan.” (Hébérù 2:1)
Ọ̀RỌ̀ ÌSÀÁJÚ
Ni ori ikinni lẹta si awọn Heberu ti a n gbe yẹwo, a ri wipe Jesu ni ẹni naa ti Ọlọrun ti gbe ga ju gbogbo nkan ti O da lọ, yala awọn nkan ti a fojuri ni tabi eyi ti a ko fojuri. Bi a tilẹ tun ṣe ri, a ti gbe Jesu ga ju gbogbo awọn angẹli lọ, yala awọn angẹli Ọlọrun ni tabi Eṣu ati awọn angẹli rẹ. Gbogbo wọn patapata ni Jesu ga, ti O si tun tobi julọ. Nitorina, ti a ba ni ẹni ti o yẹ ki a fi tọkan-tọkan tẹti si nkan ti o n sọ, Jesu ni ẹni naa. Yatọ si eyi, titori gbogbo awọn eniyan patapata, ati Ju ati Keferi, ni a ṣe ran Jesu wa saye. Ko wa yẹ ki a jẹ ki wiwa rẹ saye fun wa ja si asan. Awọn nkan wọnyi si ni onkọwe iwe Heberu tẹsiwaju lati sọ fun wa ni ori keji lẹta naa. Yoo si dara pupọ ti a ba kiyesi si awọn nkan wọnyi, ti a si bẹrẹ si ni ṣe amulo wọn lọna ti o peye.
A NÍLÒ ÀFỌKÀNSÍ
Wayi o, ki ni idi ti o fi ṣe pataki fun wa lati mu ọrọ Jesu ni ọkunkundun ju ọrọ ẹnikẹni lọ? Onkọwe lẹta si awọn Heberu la wa lọyẹ daradara lori eyi nipa sisọ awọn nkan wọnyi:
“NITORINA o yẹ ti awa iba mã fi iyè gidigidi si ohun wọnni ti awa ti gbọ́, ki a má bã gbá wa lọ kuro ninu wọn nigbakan. Nitori bi ọ̀rọ ti a ti ẹnu awọn angẹli sọ ba duro ṣinṣin, ati ti olukuluku irekọja ati aigbọran si gbà ẹsan ti o tọ́; Awa o ti ṣe là a, bi awa kò ba nani irú igbala nla bi eyi; ti àtetekọ bẹ̀rẹ si isọ lati ọdọ Oluwa, ti a si fi mulẹ fun wa lati ọdọ awọn ẹniti o gbọ́; Ọlọrun si nfi iṣẹ àmi ati iṣẹ iyanu, ati onirũru iṣẹ agbara, ati ẹ̀bun Ẹmí Mimọ́ bá wọn jẹri gẹgẹ bí ifẹ rẹ̀?” (Hébérù 2:1-4)
Njẹ o ri bayẹn? O yẹ, o ṣe pataki ki a ma fi iye gidigidi si awọn nkan ti Ọlọrun n tipasẹ Jesu ba wa sọ. Ranti wipe ni ori kinni lẹta yi, a jẹ ki o ye wa pe Jesu, Ọmọ Ọlọrun, ni ẹni naa ti Ọlọrun n tipasẹ rẹ ba gbogbo eniyan sọrọ lọwọlọwọ yi, ni awọn ọjọ ikẹyin wọnyi. Jesu yi si ni ajogun ohun gbogbo ti Ọlọrun da, itansan ogo Ọlọrun ati aworan Ọlọrun funrarẹ. Nitorina, bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun ma n tipasẹ awọn angẹli, ti wọn jẹ ẹmi ọrun, ba awọn eniyan sọrọ, Jesu ga, O si tun ni agbara ati aṣẹ ju gbogbo wọn lọ. Idi akọkọ si ni yi ti a fi nilo lati fi iye ati ọkan si ohunkohun ti O ba n sọ fun wa.
Idi ekeji ti a fi nilo lati fi iye ati ọkan si ohun yowu ti Jesu ba n sọ fun wa ni ki a ma ba gba wa kuro lọdọ rẹ, bi omi ti le gba ọkọ oju-omi ti a ko ba sọ mọlẹ kuro ni etido. Nipa gbigba Jesu gbọ, igbala ati irapada ti o peye ti tọ wa wa, a si tun ti fi idi wa mulẹ sinu otitọ Ọlọrun. Ṣugbọn a nilo lati duro ṣinṣin ninu awọn nkan ti a ti gbọ lẹnu rẹ, ti a si ti gbagbọ. Aijẹbẹ, o ṣeeṣe ki awọn nkan ti a ti dirọmọ tẹlẹ tabi awọn ẹkọ tabi ẹsin ajeji miran gba wa danu kuro ni ààyè wa, nibiti igbala ti o peye, ti o si daju ti jẹ ti wa.
Fun awọn Heberu Kirisitiẹni ti a kọkọ kọ lẹta yi si, ofin Mose ati gbogbo awọn ẹbọ ti o sọrọ mọ ni o fẹ ma ba Jesu fagagbaga ninu aye wọn. A wa n jẹ ki o ye wọn pe niwọn igba ti Jesu ti ga ju gbogbo awọn angẹli lọ, ti o ṣi jẹ wipe awọn angẹli yi gan naa ni a lo lati fun Mose ni ofin yi, wọn ko gbọdọ fi aye gba ohunkohun ti o ni i ṣe pẹlu ofin Mose lati gba wọn danu kuro ninu igbala ti wọn ti ri gba ninu Kirisiti Jesu. (Wo: Ìṣe Àpọ́sítélì 7;53; Gàlátíà 3:19)
Bi onkọwe yi ti ṣe sọ siwaju, ewu nla wa ninu ki a fi aye gba ohunkohun lati gba wa danu kuro ninu igbagbọ ninu Kirisiti Jesu. Lọna wo? O jẹ ki o ye wa pe niwọn igba ti awọn ti o ṣe aigbọran si ọrọ Ọlọrun ti o tipasẹ awọn angẹli tọ wọn wa ba ri ijiya ti o peye gba nitori aigbọran wọn, ṣe ko wa ni buru si fun awọn ti o ba ṣe aigbọran si Jesu Ọmọ Ọlọrun, ajogun ohun gbogbo ti Ọlọrun da? O di dandan ki O buru si fun wọn.
Jesu funrarẹ ni ẹni naa ti O kọkọ bẹrẹ si ni waasu nipa igbala ti o peye ti Ọlọrun fẹ fun wa si araye. Lẹyin rẹ ni awọn iranṣẹ rẹ ti wọn ni anfaani lati jẹri si igbe aye rẹ ati iku rẹ naa tẹsiwaju lati ma waasu nipa igbala naa fun araye. Yatọ si eyi, Ẹmi Ọlọrun gan tun wa n jẹri si ọrọ igbala ti a n sọ yi nipa ṣiṣe oniruuru iṣẹ ami, iṣẹ iyanu, iṣẹ agbara ati ipinfunni awọn ẹbun Ẹmi, ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ. Ṣe a wa le pa ọrọ nipa igbala yi ti lati wa igbala ni ọna miran ki iyọnu ma wa fun wa? Ko ṣeeṣe.
Lẹyin ti o ti fi idi eyi mulẹ fun wa, onkọwe lẹta yi wa tẹsiwaju lati jẹ ki o ye wa pe titori awa eniyan ni Jesu ṣe wa saye lati ṣiṣẹ igbala, ko ki i ṣe nitori awọn angẹli. Nitorina, awa, yala Juu tabi Keferi ni wa, ni o nilo igbala, ko ki i ṣe awọn angẹli. Bẹẹ si tun ni, awa ni Ọlọrun fẹ ki a jogun aye tuntun ti O fẹ gbe kalẹ nigba ti asiko ba to, ko ki i ṣe awọn angẹli. Wo bi o ti ṣe ṣalaye awọn nkan wọnyi:
“Nitoripe ki iṣe abẹ awọn angẹli li o fi aiye ti mbọ̀ ti awa nsọrọ rẹ̀ si. Ṣugbọn ẹnikan sọ nibikan wipe, Kili enia ti o fi nṣe iranti rẹ̀, tabi ọmọ enia, ti o mbẹ̀ ẹ wò? Iwọ dá a rẹlẹ̀ diẹ jù awọn angẹli lọ; iwọ fi ogo ati ọlá dé e li ade, iwọ si fi i jẹ olori iṣẹ ọwọ́ rẹ: Iwọ fi ohun gbogbo sabẹ ẹsẹ rẹ̀. Nitori niti pe o fi ohun gbogbo sabẹ rẹ̀ kò kù ohun kan ti kò fi sabẹ rẹ̀. Ṣugbọn nisisiyi awa kò iti ri pe a fi ohun gbogbo sabẹ rẹ̀. Awa ri ẹniti a dá rẹlẹ̀ diẹ jù awọn angẹli lọ, ani Jesu, ẹniti a fi ogo ati ọlá dé li ade nitori ijiya ikú; ki o le tọ́ iku wò fun olukuluku enia nipa õre-ọfẹ Ọlọrun. Nitoripe o yẹ fun u, nitori ẹniti ohun gbogbo ṣe wà, ati nipasẹ ẹniti ohun gbogbo wà, ni mimu awọn ọmọ pupọ̀ wá sinu ogo, lati ṣe balogun igbala wọn li aṣepé nipa ìjiya. Nitori ati ẹniti nsọni di mimọ́ ati awọn ti a nsọ di mimọ́, lati ọdọ ẹnikanṣoṣo ni gbogbo wọn: nitori eyiti ko ṣe tiju lati pè wọn ni arakunrin, Wipe, Emi ó sọ̀rọ orukọ rẹ fun awọn ará mi, li ãrin ijọ li emi o kọrin iyìn rẹ. Ati pẹlu, Emi o gbẹkẹ̀ mi le e. Ati pẹlu, Kiyesi i, emi ati awọn ọmọ ti Ọlọrun fifun mi.” (Hébérù 2:5-13)
Ṣe o ri bayẹn? Nigba ti Ọlọrun kọkọ da aye yi ati ọrun, abẹ eniyan ni o fi akoso ohun gbogbo ti o da si. Ko si wa si ohunkohun ti Ọlọrun ko fi si abẹ iṣakoso rẹ, pẹlupẹlu awọn angẹli. A si ri aridaju eyi ninu akọsilẹ Iwe Mimọ. Ṣugbọn lọwọlọwọ yi a ko ri ohun gbogbo ni abẹ iṣakoso eniyan. Ki ni idi? Iṣubu wa sinu ẹṣẹ ninu ọgba Edẹni ni idi. Eyi lo fa a ti a n fi sa fun awọn ẹranko ati ti awọn nkan ti a fi ọwọ ara wa da fi n le dẹru bawa tabi ṣe wa ni ijamba. Idi naa si tun ni yi ti ẹru fi n ma n ba wa ti a ba ṣalabapade awọn angẹli. (Wo: Sáàmù 8:3-8; 1Kọrinti 6:3)
Amọ ṣa o, bi a ko tilẹ ri ohun gbogbo ni abẹ isakoṣo eniyan lọwọlọwọ yi, a ni anfaani lati ri Jesu, ẹni ti o jẹ aṣoju gbogbo eniyan, ni ipo Oluwa lori ohun gbogbo. Bawo ni o ṣe di Oluwa lori ohun gbogbo? Nipa rirẹ ara rẹ silẹ fun ijiya ẹṣẹ wa ni!
Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, Jesu ko dẹṣẹ rara nigba ti O gbe ile aye. Idi si ni pe ko si irugbin ẹṣẹ ninu aye rẹ. Yatọ si eyi, nipasẹ agbara Ẹmi Mimọ ni O ṣe n ṣe ohun gbogbo. Nitorina, O gbe ile aye lati fi apẹrẹ bi Ọlọrun ṣe fẹ ki eniyan ma a gbe ile aye han wa, eyi ti o jẹ idi akọkọ ti Ọlọrun fi ran wa saye. Amọ ki O ba le rawapada, O nilo lati jiya fun ẹṣẹ wa. Eyi ni o jẹ aṣepe iṣẹ iranṣẹ rẹ fun ọmọniyan, ti i ṣe idi keji ti a fi ran wa saye.
Niwọn igba ti O si ti ku fun ẹṣẹ wa, O ti balogun igbala wa ati Ẹni naa ti O n sọ ni di mimọ. Nigba ti O si ti wa sọ awa ti a gbagbọ ninu rẹ di mimọ, ko le lailai ti i loju lati pe wa ni arakunrin ati arabinrin rẹ. Idi si ni pe awa naa ti di ọmọ Ọlọrun ati ara ile rẹ. Ti ko ba si ti i loju lati ṣe eyi, ko yẹ ki o ti awa naa loju lati pe ni arakunrin wa, yatọ si pe ki a pe ni Oluwa wa.
Onkọwe lẹta yi wa tun tẹsiwaju lati jẹ ki o ye awọn Heberu tabi Juu ti o kọkọ ri lẹta naa gba pe ọrọ ẹnu lasan kọ ni pe Jesu jẹ arakunrin wọn o, bi O tilẹ jẹ wipe Ọmọ Ọlọrun ni. Idi si ni pe eniyan pọnbele ni O jẹ pẹlu. Iyẹn jasi pe Oun naa jẹ alabapin ni ara ati ẹjẹ, gẹgẹ bi gbogbo awọn ọmọniyan yoku. Eyi ni o jẹ ki O le ku nipa ti ara. Ka sọ wipe Jesu ko ki i ṣe eniyan ni, ko ni le ku nipa ti ara, bi a tilẹ gbiyanju lati pa a.
Amọ eniyan, ẹlẹran-ara bi ti wa ni Jesu Kirisiti jẹ. Idi si ni yi ti O fi le ku fun ẹṣẹ wa. Iwọ naa wo nkan ti onkọwe yi sọ siwaju si lori eyi:
“Njẹ niwọn bi awọn ọmọ ti ṣe alabapin ara on ẹ̀jẹ, bẹ̃ gẹgẹ li on pẹlu si ṣe alabapin ninu ọkanna; ki o le ti ipa ikú pa ẹniti o ni agbara ikú run, eyini ni Eṣu; Ki o si le gbà gbogbo awọn ti o ti itori ibẹru iku wà labẹ ìde lọjọ aiye wọn gbogbo. Nitoripe, nitõtọ ki iṣe awọn angẹli li o ṣe iranlọwọ fun, ṣugbọn irú-ọmọ Abrahamu li o ṣe iranlọwọ fun. Nitorina o yẹ pe ninu ohun gbogbo ki o dabi awọn ará rẹ̀, ki o le jẹ alãnu ati olõtọ Olori Alufa ninu ohun ti iṣe ti Ọlọrun, ki o le ṣe etutu fun ẹ̀ṣẹ awọn enia. Nitori niwọnbi on tikararẹ̀ ti jiya nipa idanwo, o le ràn awọn ti a ndan wo lọwọ.” (Hébérù 2:14-18)
Njẹ o ri bayẹn? Eniyan pọnbele ni Jesu jẹ pẹlu, bi o tilẹ jẹ wipe Ọmọ Ọlọrun tun ni. Idi ni yi, bi a ti ṣe sọ tẹlẹ, ti O fi le ku fun wa. O wa ku fun wa lati ṣe etutu fun ẹṣẹ wa ati lati gba wa kuro lọwọ agbara iku ati ẹ̀rù iku. Lọna wo? Nipa gbigba agbara lọwọ Satani, ẹni ti o ti n lo agbara iku lori awọn ọmọ eniyan! Nitorina, awa ti a jẹ ọmọ Ọlọrun ko gbọdọ fi aye gba Satani lati fi iku dẹru ba wa. Nitoripe ko ni agbara mọ lori aye wa lati pa wa, ti Ọlọrun ko ba fa wa le e lọwọ. Ṣe Ọlọrun yoo wa ṣadede fa ọmọ rẹ kankan le Satani lọwọ lalai nidi? Ko jẹ jẹ bẹ!
Ki a ranti pe idi ti Ọlọrun ṣe fa Jesu akọbi gbogbo awọn Ọmọ rẹ le iku lọwọ ni ki O ba a le jere ọmọ pupọ jọjọ si i. Nitorina, ti Ọlọrun ba nilo lati fa ọmọ rẹ kankan le iku lọwọ, lalai ṣe fun ijiya fun gbigbe ninu ẹṣẹ, O ni lati jẹ wipe O ni nkan rere kan ti O fẹ tipasẹ eyi fayọ ni. Nitorina, a ko ni lati bẹru iku nipa ti ara mọ. Jesu ti ṣẹgun rẹ fun wa. Nṣe ni ki a kan fi ọkan wa si gbigbe aye wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun ki a ma ba ku iku ẹmi ati iku ayeraye.
Bi a tun se wa ri ninu awọn ẹsẹ bibeli wọnyi, ko ki i ṣe awọn angẹli ni Jesu ku fun o, bikoṣe iru awọn ọmọ Aburahamu ati gbogbo awọn eniyan yoku. Nitorina, awa ni igbala wa fun, ko ki i ṣe awọn angẹli. Idi si ni yi ti o fi jẹ awa ni a n waasu iyinrere fun.
Yatọ si eyi, onkọwe iwe Heberu yi fẹ ki a mọ daju pe Jesu ko kan ku fun ẹṣẹ wa nikan o; O tun wa laaye fun wa lati ran wa lọwọ lati bori gbogbo idanwo ẹṣẹ ati eṣu. Ṣe O wa wa nipo ẹni ti O le ran wa lọwọ lati bori idanwo ẹṣẹ ati eṣu? Bẹẹni! Lọna wo? Idi ni pe niwọn igba ti o jẹ wipe ẹlẹran-ara bi ti wa ni Oun naa jẹ nigba ti O gbe ile aye, gbogbo awọn idanwo ti awọn eniyan le dojukọ ni Oun naa dojukọ, ti O si bori. Nitorina, O le ba wa lopọ pẹlu oye, ododo ati ifarada, gẹgẹ bi Alufa wa niwaju Ọlọrun, lati ran wa lọwọ lati bori gbogbo igbogun ẹṣẹ lori ọkan wa. Eyi ko wa kamọmọ bi? O kamọmọ!
Ni akotan, nkan ti a n jẹ ki o ye wa ni ori ikeji iwe Heberu ni pe a nilo lati fi ọkan si ohun yowu ti Jesu Ọmọ Ọlọrun ba n sọ fun wa ati gbogbo awọn nkan ti O ti ṣe fun wa. Eyi ni yoo jẹ ki a le gbe igbe aye ti o wu Ọlọrun, ki a si ma gba wa danu kuro ninu igbalat ti a ti rigba lọwọ rẹ nipasẹ igbagbọ wa ninu rẹ.
ÌBÉÈRÈ
– Ki ni o fi Jesu si ipo ẹni ti o yẹ lati ku fun ẹṣẹ araye?
– Bawo ni o ṣe ṣe pataki to fun wa lati mu Jesu ni ọkunkundun?
Láti ọwọ́ Johnson O. Lawal
Copyright © 2025 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)
ÀKỌ́RÍ: HÉBÉRÙ 1- ỌMỌ JU ÀWỌN ÁNGẸ́LÌ LỌ | ÀYỌKÀ: HÉBÉRÙ 1:1-14 | ỌJỌ́RÚ 29, Ọ̀WÀRÀ 2025
ÀKỌ́SÓRÍ: “Ẹniti iṣe itanṣan ogo rẹ̀, ati aworan on tikararẹ, ti o si nfi ọ̀rọ agbara rẹ̀ mu ohun gbogbo duro, lẹhin ti o ti ṣe ìwẹnu ẹ̀ṣẹ, o joko li ọwọ́ ọtún Ọlánla li oke.” (Hébérù 1:3)
Ọ̀RỌ̀ ÌSÀÁJÚ
Iwe Heberu jẹ ọkan pataki lara awọn iwe inu Bibeli ti o kọ wa ni bi a ti ṣe n ṣe amulo oore-ọfẹ Ọlọrun lati gbe igbe aye ti O fẹ ki a gbe. A ko le sọ ni pato ẹni ti o kọ iwe yi. Idi si ni pe ẹni naa ko fi ara rẹ han yala ni ibẹrẹ tabi opin iwe naa. Lotitọ, ọpọ awọn onimọ-ijinlẹ ninu bibeli ni o gbagbọ pe Apọsiteli Pọọlu ni o kọ iwe yi. Idi wọn si ni pe bi a ti ṣe kọ iwe naa farajọ bi Pọọlu ti ṣe ma n kọ awọn lẹta rẹ.
Ki wa ni idi ti ko fi fi orukọ rẹ si? Igbagbọ wọn ni pe ko fi orukọ rẹ si nitoripe awọn Juu tabi Heberu ti o jẹ Kirisitiẹni kaakiri agbaye nigbanaa ni o kọ ọ si. Ko si wa fẹ ki awọn adari ẹsin Juu mọ pe oun ni o n kọ ọ, ki inunibini wọn si ma ba a tu burukẹ si. Ṣe otitọ wa ni awọn alaye wọnyi? A ko le sọ. A ṣa mọ wipe bi a ti ṣe kọ iwe naa farajọ bi Pọọlu ti ma n kọwe nitootọ. A si tun mọ wipe niwọn igba ti iwe naa ti wa ninu bibeli, a jẹ wipe Ọlọrun fẹ ki a mọ otitọ inu rẹ ni. Boya Pọọlu lo wa kọ o tabi ẹlomiran, ti wa ni ki a kọ ẹkọ ti Ẹmi Ọlọrun fẹ ki a ti ara iwe naa kọ, ki a si fi ara wa jin lati ṣe amulo rẹ.
Ki wa ni idi ti a fi kọ iwe yi si awọn Kiristiẹni ti o jẹ Heberu tabi Juu igbaani? A kọ iwe naa si wọn, gẹgẹ bi a ti ri ninu rẹ, lati pe awọn ti wọn ti n ṣe iyemeji lori igbagbọ wọn ninu Jesu Kirisiti pada wale. Bi a ti ṣe fi ye wa ninu Iwe Iṣe Apọsiteli ati awọn akọsilẹ itan ẹṣin Kirisitiẹni miran, ko rọrun rara ni asiko awọn apọsiteli igbaani fun awọn ti o jẹ Juu lati gba Kiristi gbọ ati lati ma gbe igbe aye Kirisitiẹni. Idi si ni pe inunibini lati ọdọ awọn Juu akẹgbẹ wọn pọ jọjọ. A wa ri awọn Kirisitẹni Juu igba naa ti o tu n woye pe boya aṣiṣe ni fun awọn lati pa ofin Mose ati awọn ẹbọ ti o sorọ mọ-ọn ti gẹgẹ bi ọna lati jẹ ẹni ti o yẹ niwaju Ọlọrun ati lati gba Jesu gbọ gẹgẹ bi Kirisiti ati Olugbala wọn. Eyi si n kọ wọn lominu, o si tun n fun wọn ni irẹwẹsi ọkan. A wa kọ iwe yi si wọn lati fi oye ẹni ti Jesu jẹ han wọn kedere, lati fi awọn ọna ti O gba ga ju awọn angẹli, Mose, Aaroni ati bẹẹbẹẹ lọ han wọn ati lati jẹ ki wọn mọ pataki iṣẹ iranṣẹ ti Ọlọrun ran waye wa ṣe fun irapada wọn. Awọn nkan ti a si la kalẹ ninu iwe naa lori awọn nkan wọnyi wulo gidigidi fun awa naa, ki ba a le fi idi wa mulẹ ninu otitọ ọrọ Ọlọrun.
ỌMỌ JU ÀWỌN ÁNGẸ́LÌ LỌ
Wayi o, nkan akọkọ ti onkọwe lẹta si awọn Heberu ṣe ni lati fi oye ẹni ti Jesu Kirisiti ọmọ Ọlọrun jẹ han wọn ati lati tun la wọn lọyẹ awọn ọna ti Jesu gba ga ju gbogbo awọn angẹli, iyẹn awọn ẹmi ọrun, lọ. Iwọ naa wo diẹ lara awọn nkan ti o kọkọ sọ;
“ỌLỌRUN, ẹni, ni igba pupọ̀ ati li onirũru ọna, ti o ti ipa awọn woli ba awọn baba sọ̀rọ nigbãni. Ni ikẹhin ọjọ wọnyi o ti ipasẹ Ọmọ rẹ̀ ba wa sọ̀rọ, ẹniti o fi ṣe ajogun ohun gbogbo, nipasẹ ẹniti o dá awọn aiye pẹlu; Ẹniti iṣe itanṣan ogo rẹ̀, ati aworan on tikararẹ, ti o si nfi ọ̀rọ agbara rẹ̀ mu ohun gbogbo duro, lẹhin ti o ti ṣe ìwẹnu ẹ̀ṣẹ, o joko li ọwọ́ ọtún Ọlánla li oke; O si ti fi bẹ̃ di ẹniti o sàn ju awọn angẹli lọ, bi o ti jogun orukọ ti o ta tiwọn yọ.” (Hébérù 1:1-4)
Pẹlu nkan ti a ri ninu awọn ẹṣẹ bibeli yi, a ri daju pe oniruuru ọna ni Ọlọrun n gba ba awọn eniyan sọrọ. Ki a tilẹ sọ otitọ, O ti lo oniruuru ọna lati ba awọn eniyan igbaani sọrọ. Ọkan pataki lara awọn ọna ti O si lo ju lati ba wọn sọrọ ni lati ẹnu awọn wolii rẹ. Amọ yatọ si lilo awọn wolii lati ba awọn eniyan sọrọ, Ọlọrun tun ma n lo awọn angẹli, iran-ọrun ati ala lati ba wọn sọrọ. Lafikun, Ọlọrun ma n ba awọn eniyan sọrọ taara-taara lati ọrun wa, bi igba ti o jẹ wipe o wa pẹlu wọn laye yi. A si ri akọsilẹ apẹrẹ awọn nkan wọnyi loriṣiriṣi ninu Iwe Mimọ.
Amọ ṣa o, lọwọlọwọ ti a wa yi, ni awọn ọjọ ikẹyin yi, gẹgẹ bi onkọwe yi ti fẹ ki o ye wa, nipasẹ Jesu Kirisiti, ọmọ Ọlọrun ti O ran wa saye, ni O n ṣe n ba wa sọrọ. Bẹ ṣi ni a ri akọsilẹ awọn nkan ti O n ba wa sọ lati ipasẹ rẹ ninu Iwe Mimọ. Ara idi niyi ti O fi jẹ wipe ọna ti o ṣe pataki julọ lati mọ Ọlọrun ati ifẹ rẹ fun wa ni ki a fi ara wa jin fun Iwe Mimọ. Idi si ni wipe ninu iwe yi ni akọsilẹ ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu ifẹ Ọlọrun fun wa wa.
Ki a ma fọrọgun, koko nkan ti onkọwe lẹta si awọn Heberu wa fẹ ki a dimu ni ori ikinni lẹta naa ti a n gbe yẹwo ni idi ti a fi nilo lati kiyesi ohun gbogbo ti Ọlọrun n tipasẹ ọmọ rẹ ba wa sọ ju ohun yowu ti wolii, angẹli, ala tabi iran kan le ma sọ fun wa lọ. Bi a ti ṣe sọ saaju, ododo ni pe Ọlọrun ma n ba awọn eniyan sọrọ lati ipasẹ awọn wolii, ala, iran ati angẹli. Amọ a gbọdọ gbe ohun yowu ti O ba tipasẹ ọmọ rẹ ba wa sọ leke gbogbo ohun ti a le gbọ tabi mọ nipasẹ awọn wolii, angẹli, ala tabi iran. Eyi jasi pe a gbọdọ gbe ohun yowu ti a ba tipasẹ awọn ọna wọnyi gbọ ti o ba tako ohun ti Ọlọrun n tipasẹ ọmọ rẹ ba wa sọ ju ṣẹgbẹ kan.
Ki wa ni idi ti a fi gbọdọ ṣe eyi? Idi akọkọ ni pe Jesu Kirisiti ọmọ Ọlọrun ni O fi ṣe ajogun ohun gbogbo ti O da ati ti O ni, laye ati lọrun, ni asiko yi ati ni asiko ti o n bọ. Nitorina, aṣẹ ti Jesu ba pa ni abẹ ge; ohunkokun ti O ba si sọ ni yo bori ohun yowu ti ẹnikẹni le sọ tabi ṣe.
Idi ekeji ni pe Jesu ni itansan ogo Ọlọrun ati awọran bi Ọlọrun tikararẹ ṣe ri ni iwa ati ni iṣe. Nitorina, ohunkohun ti Jesu ba ṣe, Ọlọrun ni O ṣe. Ohunkohun ti O ba si sọ, Ọlọrun ni O sọ. A si tun wa jẹ ki o ye wa pe ọrọ rẹ ni agbara lati fi idi ohun gbogbo mulẹ ati lati gbe ohun gbogbo ro. Ṣe o wa yẹ ki a mu ọrọ rẹ ni pataki tabi ko yẹ? O yẹ!
Idi ẹkẹta ni pe lẹyin igba ti Jesu ti ṣe etutu fun ẹṣẹ araye, O joko si ọwọ ọtọ Ọlọrun ni ọrun. Itunmọ eyi ni pe ipo alaṣẹ lori ohun gbogbo, laye, lọrun ati ni isalẹ-ilẹ, ni Jesu wa bayi. Nitorina, ohun gbogbo gbọdọ tẹriba fun aṣẹ rẹ. O wa yẹ ni ẹni ti a gbọdọ kasi tabi ko yẹ? O yẹ!
Nitori eyi, onkọwe lẹta yi tẹsiwaju lati jẹ ki o ye wa pe Jesu san ju gbogbo awọn angẹli lọ. Wayi o, ọrọ ti a lo ninu bibeli Yoruba ti mo n lo yi lati ṣapejuwe bi Jesu ti ṣe jẹ si awọn angẹli bu nkan ti onkọwe lẹta yi fẹ ki o ye ku lọna ti o ga. Nkan ti o fẹ ki a mọ kọ ni pe Jesu san ju awọn angẹli lọ. Nkan ti o fẹ ki a mọ ni pe Jesu ga ni gbogbo ọna ju awọn angẹli lọ. Eyi jasi pe ko si aye fun ìfagagbága kankan laarin Oun ati awọn angẹli. Nitorina, ibi ti Jesu ba ti n sọrọ, nṣe ni awọn angẹli, yala ti Ọlọrun ni tabi ti eṣu, gbọdọ dakajẹ ni. (Wo: 1Pétérù 3:22)
Lọna wo wa ni Jesu fi ga ju awọn angẹli lọ? A ti sọ ṣiwaju pe ni gbogbo ọna ni O fi ga ju wọn lọ. Ṣibesibẹ, onkọwe lẹta yi fi han wa lati inu Iwe Mimọ awọn ọna ti Jesu gba ga tabi tobi ju awọn angẹli lọ. Wo awọn nkan ti o sọ:
“Nitori ewo ninu awọn angẹli li o wi fun rí pe, Iwọ li Ọmọ mi, loni ni mo bí ọ? Ati pẹlu, Emi yio jẹ Baba fun u, on yio si jẹ Ọmọ fun mi? Ati pẹlu, nigbati o mu akọbi ni wá si aiye, o wipe, Ki gbogbo awọn angẹli Ọlọrun ki o foribalẹ fun u. Ati niti awọn angẹli, o wipe, Ẹniti o dá awọn angẹli rẹ̀ li ẹmí, ati awọn iranṣẹ rẹ̀ li ọwọ́ iná. Ṣugbọn niti Ọmọ li o wipe, Itẹ́ rẹ, Ọlọrun, lai ati lailai ni; ọpá alade ododo li ọpá alade ijọba rẹ. Iwọ fẹ ododo, iwọ si korira ẹ̀ṣẹ; nitorina li Ọlọrun, ani Ọlọrun rẹ, ṣe fi oróro ayọ̀ yan ọ jù awọn ẹgbẹ rẹ lọ. Ati Iwọ, Oluwa, li atetekọṣe li o ti fi ipilẹ aiye sọlẹ; awọn ọrun si ni iṣẹ ọwọ́ rẹ: Nwọn ó ṣegbe; ṣugbọn iwọ ó wà sibẹ, gbogbo wọn ni yio si gbó bi ẹwu; Ati bi aṣọ ni iwọ o si ká wọn, a o si pàrọ wọn: ṣugbọn bakanna ni iwọ, ọdún rẹ kì yio si pin. Ṣugbọn ewo ninu awọn angẹli li o sọ nipa rẹ̀ ri pe, Joko li ọwọ́ ọtún mi, titi emi o fi sọ awọn ọtá rẹ di apoti itisẹ rẹ? Ẹmí ti njiṣẹ ki gbogbo wọn iṣe, ti a nran lọ lati mã jọsin nitori awọn ti yio jogun igbala?” (Hébérù 1:5-14)
Ki ni awọn nkan ti a ri fayọ ninu awọn nkan ti a kọ silẹ yi? Akọkọ ni pe ko si ọkankan lara awọn angẹli ti Ọlọrun fi igba kankan pe ni ọmọ bibi rẹ. Ṣugbọn O pe Jesu ni ọmọ rẹ ati ajogun ohun gbogbo ti O da ati ti O ni. Nitorina, ko si angẹli kankan ti o le duro lẹgbẹ Jesu tabi ba fi agagbága lọna kankan. (Wo: Sáàmù 2:7)
Nkan ekeji ti a ri ni wipe Ọlọrun funrarẹ pasẹ fun gbogbo awọn angẹli lati foribalẹ fun Jesu. Iyẹn jasi pe awọn angẹli, gbogbo wọn patapata, pẹlupẹlu Satani, ni lati foribalẹ niwaju Jesu ni igbakugba ti wọn ba farahan niwaju rẹ. Idi si ni pe Ọlọrun ti gbe ga ju gbogbo wọn lọ gẹgẹ bi ọmọ rẹ si ọwọ ọtun rẹ ati sori itẹ ologo, itẹ ti ki i ṣa, itẹ ayeraye, O si tun ti fun ni orukọ ti bori gbogbo orukọ. Nitorina, gbogbo wọn gbọdọ wolẹ ti wọn ba ti n gbọ orukọ rẹ gẹgẹ bi Oluwa wọn. (Wo: Éfésù 1:20-23; Fílípì 2:9-11)
Onkọwe lẹta yi wa kasẹ gbogbo nkan ti o n sọ lori afiwe Jesu ati awọn angẹli nilẹ nipa jijẹ ki o ye wa pe iranṣẹ ni awọn angẹli jẹ fun gbogbo awọn ti Ọlọrun yan lati jogun igbala ti Jesu ti fi ẹmi rẹ ra fun wọn. Nitori eyi, ko yẹ ki a ri ẹnikẹni ti yoo gbe angẹli kan si ipo Jesu tabi gbe angẹli kankan ga ju Jesu lọ ninu aye rẹ. Ibọriṣa ni eyi yoo jasi fun irufẹ ẹni bẹẹ. Ijiya ti o ga ni yoo si tẹle. A si apẹrẹ eyi ninu iha ti awọn angẹli ti Johanu fẹ tẹriba fun ni asiko kan kọ si nkan ti o fẹ ṣe. Wọn kilọ fun pe ki o ma ṣe dan wo. Idi si ni pe iranṣẹ lasan ni wọn. Ọlọrun ati Jesu nikan ni wọn lẹtọ lati gba itẹriba ẹnikẹni. (Wo: Ifihan 1:10 & 22:10)
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Ni akotan, onkọwe lẹta si awọn ara Heberu bẹrẹ lẹta naa lati jẹ ki o ye wa pe ipo Oluwa ati Alaṣẹ lori ohun gbogbo ti Ọlọrun da, ati aye ti a le fojuri ati aye ti a ko le fojuri, ni Jesu Kirisiti wa. Idi si ni pe ọmọ Ọlọrun ni Oun n ṣe. Nitorina, ko ki i ṣe aṣiṣe ni fun ẹnikẹni lati gba a gbọ ati lati gbe ọrọ rẹ leke ọrọ yowu tabi ohun yowu ti awọn ẹda Ọlọrun miran le ṣe.
ÌBÉÈRÈ
– Tani Jesu?
– Ki ni o ri sọ si fifi orukọ awọn angẹli kan gbadura?
Láti ọwọ́ Johnson O. Lawal
Copyright © 2025 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)
ÀKỌ́RÍ: 1JÒHÁNÙ 5-AṢẸ́GUN AYÉ | ÀYỌKÀ: 1JÒHÁNÙ 5:1-21 | ỌJỌ́RÚ 08, Ọ̀WÀRÀ 2025
ÀKỌ́SÓRÍ: “Awa si mọ̀ pe Ọmọ Ọlọrun de, o si ti fi òye fun wa, ki awa ki o le mọ̀ ẹniti iṣe otitọ, awa si mbẹ ninu ẹniti iṣe otitọ, ani ninu Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi. Eyi li Ọlọrun otitọ, ati ìye ainipẹkun. ” (1Jòhánù 5:20)
Ọ̀RỌ̀ ÌSÀÁJÚ
Ni ori ikẹrin lẹta akọkọ Johanu ti a wo ninu ẹkọ ti a kọ kẹyin, o ba wa sọrọ siwaju si lori pataki ki a ma rin ninu ifẹ. Idi si ni pe ifẹ ni Ọlọrun. Gbogbo awa ti a wa jẹ tirẹ ni a gbọdọ ma rin, ki a si tun ma gbe ninu ifẹ. Aijẹbẹ, a ko le sọ wipe a mọ ọn. Ni ori ikarun lẹta naa, wayi, Johanu mu gbogbo atotonu rẹ ninu lẹta yi wa si opin nipa jijẹ ki o ye wa pe gbogbo awa ti a ni igbagbọ ninu Jesu Kirisiti ni a jẹ aṣẹgun ni aye yi, ti a si tun ni iye ainipẹkun. Nitorina a ko ni lati ma gbe ninu ibẹru tabi ninu ifoya nitori iṣẹ Eṣu ninu aye yi. Awa ti bori rẹ. A kan nilo lati bẹrẹ si ni rin pẹlu afiyesi pe a ti bori rẹ ni. Ti a ba si ti n ṣe eyi, irin-ajo wa laye yi di dandan ki o jẹ irin iṣẹgun.
AṢẸ́GUN AYÉ
Ki a wa bẹrẹ si ni wo awọn nkan ti apọsiteli yi sọ fun wa lori ọrọ yi lẹsẹẹsẹ, lati ẹṣẹ ikinni, ori ikarun lẹta yi, eyi ti o lọ bayi:
“OLUKULUKU ẹniti o ba gbagbọ́ pe Jesu ni Kristi, a bí i nipa ti Ọlọrun: ati gbogbo ẹniti o fẹran ẹniti o bí ni, o fẹran ẹniti a bí nipasẹ rẹ̀ pẹlu. Nipa eyi li awa mọ̀ pe awa fẹran awọn ọmọ Ọlọrun, nigbati awa fẹran Ọlọrun, ti a si npa ofin rẹ̀ mọ́. Nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun, pe ki awa ki o pa ofin rẹ̀ mọ́: ofin rẹ̀ kò si nira. Nitori olukuluku ẹniti a bí nipa ti Ọlọrun o ṣẹgun aiye: eyi si ni iṣẹgun ti o ṣẹgun aiye, ani igbagbọ́ wa. Tani ẹniti o ṣẹgun aiye, bikoṣe ẹniti o gbagbọ́ pe Ọmọ Ọlọrun ni Jesu iṣe?” (1Jòhánù 5:1-5)
Ki ni nkan akọkọ ti Johanu sọ fun wa ninu awọn ẹsẹ yi? Oun naa ni pe gbogbo awọn ti o ba gbagbọ pe Jesu ni Kirisiti, ẹni ami ororo Ọlọrun ni, ni Ọlọrun ti tun bi. O tunmọ si wipe igbagbọ wa ninu Jesu Kirisiti ni o n sọ ni di atunbi. Gbogbo ẹni ti o ba wa sọ wipe oun fẹran Ọlọrun naa gbọdọ fẹran awọn ti Ọlọrun bi lọmọ. Ẹni ti ko ba fẹran Jesu ati awọn miran ti Ọlọrun bi lọmọ ko le sọ wipe oun fẹran Ọlọrun nitootọ. Ṣugbọn ẹni ti o ba fẹran awọn ọmọ Ọlọrun n pa ofin rẹ mọ nitoripe ifẹ ni akoja pipa ofin Ọlọrun mọ.
Johanu wa tẹsiwaju lati jẹ ki o ye wa pe pipa ofin Ọlọrun mọ ko nira. Njẹ otitọ si ni pe pipa ifẹ Ọlọrun mọ ko nira? Ti ko ba ki i ṣe otitọ, Johanu ko ni sọ fun wa pe ko nira. Nkan ti o yẹ ki a bere ni idi ti o fi sọ wipe ko nira lati ṣe ifẹ Ọlọrun. Ki si ni idi? Idi ni pe ẹnikẹni ti a ba ti tipasẹ Ọlọrun bi ti ṣẹgun aye. Ki ni idi? Idi ni awọn Jesu ti ṣẹgun aye fun un. Igbagbọ rẹ ninu Jesu si jẹ ki iṣẹgun yi da tirẹ. Eyi jasi pe nipa didi atunbi a ti jogun awọn amuyẹ ti a nilo lati le ṣe ifẹ Ọlọrun. A kan nilo lati bẹrẹ si ni ṣe amulo awọn amuyẹ wọnyi nipa adura gbigba, ṣiṣe aṣaro ninu ọrọ Ọlọrun ati nini ibaṣepọ ifẹ pẹlu awọn ọmọ Ọlọrun miran. Ti a ba si ti n ṣe eyi, nṣe ni a o bẹrẹ si ni rin pẹlu agbara lori gbogbo idojukọ aye, ẹṣẹ ati eṣu. (Wo: Jòhánù 16:33)
Siwaju si, Johanu wa tun ran wa leti irufẹ ẹni ti Jesu jẹ, iṣọkan rẹ pẹlu Ọlọrun ati Ẹmi mimọ ati iha ti o yẹ ki araye kọ si ẹri ti Ọlọrun jẹ nipa rẹ. Iwọ naa wo nkan ti o sọ:
“Eyi li ẹniti o wá, pẹlu omi ati ẹjẹ̀, ani Jesu Kristi, kì iṣe pẹlu omi nikan, bikoṣe pẹlu omi ati ẹ̀jẹ. Ẹmí li o si njẹri, nitoripe otitọ li Ẹmí. Nitoripe awọn mẹta li o njẹri li ọrun, Baba, Ọrọ̀, ati Ẹmi Mimọ; awọn mẹtẹ̃ta yi si jẹ ọ̀kan Nitoripe awọn mẹta li o njẹri, Ẹmí, ati omi, ati ẹ̀jẹ: awọn mẹtẹ̃ta sì fi ohun ṣọkan. Bi awa ba ngbà ẹ̀rí enia, ẹ̀rí Ọlọrun tobi ju: nitọri ẹri Ọlọrun li eyi pe O ti jẹri niti Ọmọ rẹ̀. Ẹniti o ba gbà Ọmọ Ọlọrun gbọ́, o ni ẹrí ninu ara rẹ̀: ẹniti kò ba gbà Ọlọrun gbọ́, o ti mu u li eke; nitori kò gbà ẹrí na gbọ́ ti Ọlọrun jẹ niti Ọmọ rẹ̀. Ẹ̀rí na si li eyi pe Ọlọrun fun wa ni ìye ainipẹkun, ìye yi si mbẹ ninu Ọmọ rẹ̀. Ẹniti o ba ni Ọmọ, o ni ìye; ẹniti kò ba si ni Ọmọ Ọlọrun, kò ni ìye. Nkan wọnyi ni mo kọwe rẹ̀ si nyin ani si ẹnyin ti o gbà orukọ Ọmọ Ọlọrun gbọ́; ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe ẹnyin ni iye ainipẹkun, ani fun ẹnyin ti o gbà orukọ Ọmọ Ọlọrun gbọ́.” (1 Jòhánù 5:6-13)
Ki ni nkan ti a kọkọ ri nipa Jesu nibiyi? Oun naa ni pe o wa pẹlu omi ati ẹjẹ. Ki ni itumọ eyi? Akọkọ, eyi tunmọ si pe eniyan ni Jesu nitootọ, ko ki i ṣe anjọnu tabi angẹli. Lotitọ, Ọlọrun ni, ẹkunrẹrẹ Ọlọrun si n gbe inu rẹ nigba ti O wa ni aye yi. Amọ ṣa o, ọmọ eniyan tun ni pẹlu. A si wa ri aridaju eyi nigba ti o ku lori igi agbelebu. Johanu, paapaa-julọ, ni anfaani lati ri eyi nigba ti Jesu wa lori igi agbelebu, ti a si ti ọkọ bọ ọ lẹgbẹ. Nitorina, ko ki i ṣe itan arosọ ni a n tẹle nigba ti a n sọ wipe a fi Jesu ṣe etutu fun ẹṣẹ wa. Nkan ti o ṣẹlẹ, ti awọn ẹlẹri si wa fun ni. (Cf. Jòhánù 19:31-35)
Yatọ si awọn eniyan ti o ba Jesu rin laye yi, njẹ a tun ri awọn ẹlẹri miran ti o n jẹri si ẹni ti O jẹ ati nkan ti O wa ṣe laye? Bẹẹni! Johanu si mẹnuba wọn. Akọkọ, o sọrọ nipa awọn ti o n jẹri ni ọrun. Awọn si ni Ọlọrun Baba funrarẹ, Ọrọ Ọlọrun ati Ẹmi Ọlọrun. Nkan kanna si ni wọn n sọ. Johanu tun sọrọ nipa awọn ti o n jẹri ni aye. Awọn si ni Ẹmi Ọlọrun, omi ara Jesu ati ẹjẹ ara rẹ ti a tu silẹ. Nkan kanna si ni awọn naa n tọka si tabi jẹri rẹ.
Ki wa ni Johanu fẹ fayọ pẹlu nkan ti< o sọ wọnyi? Oun naa ni pe ko si iyapa laarin Ọlọrun, Jesu, Ọrọ Ọlọrun ti o di ara, ati Ẹmi mimọ. Ọrọ wọn ko le lailai yatọ. Bẹẹ si ni iṣẹ ti wọn n ṣe ko le lailai tako ara wọn. Ti a ba wa ri ẹni ti o sọ wipe oun gbọ ohun Ọlọrun tabi ohun Ẹmi, ti nkan ti o gbọ si tako Ọrọ Ọlọrun ti o wa ninu Iwe mimọ, ẹni naa ti ṣi gbọ. Ti a ba si tun ri iṣẹ iyanu tabi ara kan ti o tako nkan ti Ọlọrun sọ ninu ọrọ rẹ, a ko le pe ni iṣẹ Ọlọrun tabi iṣẹ Ẹmi mimọ. Idi si ni pe iṣẹ Ọlọrun ko le lailai tako ọrọ rẹ.
Ni kukuru, Ọlọrun, Ẹmi rẹ, Ọrọ rẹ ati awọn nkan ti o ṣẹlẹ si Jesu nigba iku rẹ n jẹri pe Ọlọrun ti fun wa ni iye ainipẹkun. Iye naa si wa ninu ọmọ rẹ, Jesu Kirisiti. Ẹni ti o ba wa gba Jesu gbọ ni iye ainipẹkun. Ko ki i ṣe wipe yoo ni iye ainipẹkun. O ti ni naa nipasẹ igbagbọ rẹ ninu Jesu. Nitorina, o le reti pe ki iye yi bẹrẹ si ni ṣiṣẹ ninu aye oun, ninu agọ ara rẹ ati ninu gbogbo idawọle rẹ. Amọ ẹni ti ko ba gba Jesu gbọ ko ni iye. Yatọ si iyẹn, irufẹ ẹni bẹ ti mu Ọlọrun ni opurọ nitoriti ko gba ẹri rẹ gbọ. O si wa di dandan ki ẹni naa pada ṣegbe.
Wayi o, Johanu tẹsiwaju lati jẹ ki awa ti a gba Jesu gbọ mọ wipe a le fi igboya gbadura si Ọlọrun, ki a si ri idahun si adura wa gba nitori igbagbọ wa ninu rẹ. Amọ ṣa o, adura yowu ti a ba gba gbọdọ wa ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ. Aijẹbẹ, pabo ni yoo ja si. Wo nkan ti o sọ lori eyi:
“Eyi si ni igboiya ti awa ni niwaju rẹ̀, pe bi awa ba bère ohunkohun gẹgẹ bi ifẹ rẹ̀, o ngbọ ti wa: Bi awa ba si mọ̀ pe o ngbọ́ ti wa, ohunkohun ti awa ba bère, awa mọ̀ pe awa rí ibere ti awa ti bère lọdọ rẹ̀ gbà. Bi ẹnikẹni ba ri arakunrin rẹ̀ ti ndá ẹ̀ṣẹ ti kì iṣe si ikú, on o bère, On o si fun ni ìye fun awọn ti ndá ẹ̀ṣẹ ti ki iṣe si ikú. Ẹṣẹ kan mbẹ si ikú: emi kò wipe ki on ki o gbadura fun eyi. Gbogbo aiṣododo ni ẹ̀ṣẹ: ẹṣẹ̀ kan sì mbẹ ti ki iṣe si ikú.” (1Jòhánù 5:14-17)
Ti a ko ba gbagbe, ni ori ikẹta lẹta yi, Johanu mẹnuba nkan ti o farapẹ eyi ti o sọ nibiyi. O sọ wipe:
“Olufẹ, bi ọkàn wa kò ba dá wa lẹbi, njẹ awa ni igboiya niwaju Ọlọrun. Ati ohunkohun ti awa ba bère, awa nri gbà lọdọ rẹ̀, nitoriti awa npa ofin rẹ̀ mọ́, awa si nṣe nkan wọnni ti o dara loju rẹ̀.” (1Jòhánù 3:21-22)
A wa ri bayi pe nkan meji ọtọọtọ ni Johanu sọ wipe o le fun wa ni igboya lati gbadura si Ọlọrun, ki a si ri idahun si adura wa gba. Akọkọ ni ki ọkan wa ma da wa lẹbi, iyẹn, ki ẹri-ọkan wa mọ. Ekeji ni ki a ma gbadura ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ. Niwọn igba ti ẹri-ọkan wa ba ti mọ wipe a n ṣe ifẹ Ọlọrun, ti adura ti a n gba naa si wa ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ, Ọlọrun yoo gbọ ti wa. Yatọ si pe yoo gbọ ti wa, a o tun ri nkan naa ti a n bere lọwọ rẹ gba, bi o tilẹ jẹ idariji ẹṣẹ fun ara wa tabi fun awọn ẹlomiran ni.
O wa ṣe pataki ki oye ifẹ Ọlọrun ye wa ti a ba fẹ ma gba adura ti yoo gbọ, ti yoo si dahun. Ọna kan gbogi ti a si fi le ni oye ifẹ rẹ ni ki a joko ti Iwe mimọ. Ọna miran ti a tun fi le ni oye ifẹ rẹ ni ki a gbadura si fun ifihan rẹ. Awọn asiko a si ma wa ti a le e ma le sọ taara-taara nkan ti o jẹ ifẹ Ọlọrun ti o peye fun wa julọ lori awọn ọrọ aye wa kan, bi o tilẹ jẹ wipe a n ka bibeli. A wa nilo lati gba dura si ni irufẹ awọn asiko wọnyi ki a ba a le mọ ohun ti O jẹ ojulowo ifẹ rẹ fun wa, ki a ba a le mọ igbesẹ ti o ye ki a gbe lori rẹ.
Fun apẹrẹ, bi Johanu ti ṣe fi han ninu awọn ẹsẹ ti o wa loke yi, ifẹ Ọlọrun ni ki a ma gbadura idariji ati iye fun awọn ara wa ti o ba n dẹṣẹ. Amọ awọn ẹṣẹ kan wa ti o le jasi iku fun awọn eniyan, bi o tilẹ jẹ wipe gbogbo aiṣododo ni ẹṣẹ. Ti ẹṣẹ ti eniyan n da ba wa jẹ eyi ti yoo jasi iku fun, Johanu ni a ko nilo lati gbadura idariji ati iye fun ẹni naa. Idi si ni pe Ọlọrun le ma gbọ tabi dahun.
Bawo ni a ṣe wa fẹ mọ ẹṣẹ ti yoo jasi iku tabi eyi ti ko ni jasi iku fun eniyan? A ko le e mọ ti Ọlọrun funrarẹ ko ba fi han wa. Oniruuru ẹṣẹ, gẹgẹ bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ni o ti ja si iku fun awọn eniyan. Arekereke ṣiṣe, iyanijẹ, aibọwọ fun Ọlọrun, igberaga, agbere ati bẹẹbẹẹ lọ ni a ri wipe Ọlọrun ṣe idajọ wọn pẹlu iku ninu bibeli. Nitorina, a ko le sọ ni pato pe ẹṣẹ ti ẹnikan n da yoo ja si iku fun tabi pe ko ni ja si iku fun, ayafi ti Ọlọrun ba fi han wa. Niwọn igba ti Ọlọrun ko ba wa fi han wa pe kiku ni ẹnikan yoo ku ati wipe ki a ma wulẹ yọ ọ lẹnu lori irufẹ ẹni bẹ, a nilo lati ma a fi adura ran awọn ara wa ti o n gbe ninu ẹṣẹ lọwọ, ki wọn ba a le ri idariji ati imupadabọsipo gba. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 38:6-10; 2Samuẹli 6:6-7; Ìṣe Àpọ́sítélì 5:1-9; Jakọbu 5:16)
Amọ ṣa o, bi Johanu ti ṣe kọ wa tẹlẹ ninu lẹta yi, ko pan dandan ki ọmọ Ọlọrun dẹṣẹ. Idi si ni pe agbara Ọlọrun n ṣiṣẹ ninu aye rẹ ati lori aye rẹ lati yọ ọ kuro ninu gbogbo ikẹkun ẹṣẹ ati ti eṣu. Amọ oye yi gbọdọ daju ṣaka ninu ọkan wa. Aijbẹ, a ko ni rin ni ibamu pẹlu rẹ. Eyi yoo si fi aye silẹ fun eṣu lati ma a yan wa jẹ ati lati ma a pọn wọn loju pẹlu ẹṣẹ ati oniruuru iwa-ika ọwọ rẹ. Wo nkan ti Johanu ba wa sọ lori eyi lati pari ọrọ rẹ ninu lẹta rẹ naa:
“Awa mọ̀ pe ẹnikẹni ti a bí nipa ti Ọlọrun kì idẹṣẹ: ṣugbọn ẹniti a bí nipa ti Ọlọrun a mã pa ara rẹ̀ mọ́, ẹni buburu nì ki si ifọwọ́kàn a. Awa mọ̀ pe ti Ọlọrun ni wa, ati gbogbo aiye li o wa ni agbara ẹni buburu nì. Awa si mọ̀ pe Ọmọ Ọlọrun de, o si ti fi òye fun wa, ki awa ki o le mọ̀ ẹniti iṣe otitọ, awa si mbẹ ninu ẹniti iṣe otitọ, ani ninu Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi. Eyi li Ọlọrun otitọ, ati ìye ainipẹkun. Ẹnyin ọmọ mi, ẹ pa ara nyin mọ́ kuro ninu oriṣa. Amin.” (1Jòhánù 5:18-21)
Ki ni awọn nkan ti Johanu sọ wipe awọn mọ ninu awọn ẹṣẹ yi? Akọkọ, o sọ wipe awọn mọ pe ẹnikẹni ti o ba jẹ ọmọ Ọlọrun ki i dẹṣẹ. Ki ni idi? Idi ni wipe Jesu yoo ma a fi gbogbo igba ṣe e yẹ lati pa ara rẹ mọ. Nitorina, eṣu ko le fọwọkan, ti ko ba gba a laye.
Nkan ekeji ti Johanu sọ wipe awọn mọ ni pe ti Ọlọrun ni gbogbo awa ti o gba Jesu gbọ jẹ. Nitorina, a ko si laba akoso tabi agbara Satani. Bi o tun ṣe fi ye, gbogbo aye yi ni o wa labẹ agbara Satani. Eyi ja si pe ko si ẹni naa ti o jẹ ti aye yi ti Satani ko le lo agbara rẹ le lori. Kiki awọn ti o jẹ ti Ọlọrun nikan ni ko le lo agbara rẹ le lori. Kiki awọn ti o jẹ ti Ọlọrun nikan ni o ti ṣẹgun rẹ. Ṣugbọn ti wọn ko ba mọ eyi, Satani ko ni dẹkun lati ma jẹ gaba lori aye wọn.
A wa dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ara idi ti O fi ran Jesu si wa ni ki O ba a le fun wa ni oye otitọ yi pe Satani ko lagbara lori aye wa mọ ati wipe Oun ni Ọlọrun otitọ. Nitorina, ko si idi fun wa lati fi ara wa jin fun ohunkohun ti o n jẹ ibọriṣa. Abalajọ ti Johanu ṣe pari ọrọ rẹ nipa sisọ wipe, “Ẹyin ọmọ mi, ẹ pa ara yin mọ kuro ninu ibọriṣa.” Idi si ni pe fifi ara wa jin fun ibọriṣa, iṣẹ-oṣo tabi iṣẹ afọṣẹ yoo kan tun fi wa si abẹ agbara Satani ni. Eyi yoo si pada ja si iparun fun wa.
Gbogbo awọn nkan wọnyi ni Johanu ati awọn ọmọ Ọlọrun aye igbaani mọ. Njẹ awa naa ha mọ wọn bi? Njẹ iwọ naa mọ wọn bi? Ti o ko ba wa mọ awọn nkan wọnyi, igbe aye Kirisitiẹni yoo nira fun ọ. Ki a tilẹ sọ otitọ, o ṣeeṣe ki o ma le gba igbe aye naa rara.
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Ni akotan, Johanu kọ lẹta rẹ akọkọ si wa lati jẹ ki a ni oye ti o peye irufẹ ẹni ti Ọlọrun jẹ ati irufẹ ibaṣepọ ti o yẹ ki a ni pẹlu rẹ ati pẹlu awọn ara wa ninu Jesu Kirisiti. Ti a o ba si ni irufẹ ibaṣepọ ti o yẹ ki a ni yi, a gbọdọ fi ọkan si gbogbo awọn nkan ti o kọ sinu lẹta naa lori awọn nkan ti Ọlọrun ti ṣe fun wa ati irufẹ ẹni ti a jẹ niwaju rẹ. Aijẹbẹ, eṣu ati ẹṣẹ yoo bori wa. Eyi si wa le fi wa han gẹgẹ bi eke onigbagbọ.
ÌBÉÈRÈ
– Bawo ni oye ẹṣẹ si iku ṣe ye ọ si?
– Ki ni itumọ pe gbogbo aye yi lo wa labẹ agbara Satani?
Lati ọwọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2025 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)
ÀKỌ́RÍ: 1JÒHÁNÙ 4-ÌFẸ́ NI ỌLỌ́RUN | ÀYỌKÀ: 1JÒHÁNÙ 4:1-21 | ỌJỌ́RÚ 10, ÒWEWÈ 2025
ÀKỌ́SÓRÍ: “Awa ti mọ̀, a si gbà ifẹ ti Ọlọrun ní si wa gbọ́. Ifẹ ni Ọlọrun; ẹniti o ba si ngbé inu ifẹ o ngbé inu Ọlọrun, ati Ọlọrun ninu rẹ̀.” (1Jòhánù 4:16)
Ọ̀RỌ̀ ÌSÀÁJÚ
Ninu awọn ẹkọ ti a ti kọ ṣaaju ninu lẹta Johanu akọkọ, a ri wipe nṣe ni o n tẹnumọ pataki ki igbesi aye wa fi han wipe ọmọ Ọlọrun ni a jẹ nitootọ. Lọna wo si ni yoo ṣe fi han? Nipa ririn ninu ododo ati ninu ifẹ! Nkan kanna yi ni o si tun wa gbe ẹnu le ni ori ikẹrin lẹta naa. O si ṣe eyi lati jẹ ki a mọ daju-ṣaka pe a ko le sọ wipe a mọ Ọlọrun tabi pe a jẹ ọmọ rẹ ti a ko ba ma a rin ninu ifẹ. Idi si ni pe ifẹ ni Ọlọrun. Ẹnikẹni ti o ba si jẹ ọmọ rẹ naa jẹ ifẹ, yoo si tun ma fi ifẹ han.
ÌFẸ́ NI ỌLỌ́RUN
Wayi o, ki Johanu to tẹsiwaju lati tẹ pataki ki a ma rin ninu ifẹ mọ wa leti, o kọkọ ran wa leti nkan kan ti o ti sọ sẹyin. Ki si ni nkan naa? Oun naa ni pe ki a ṣọra fun awọn aṣodisi-Kirisiti. Ki si ni idi? Idi ni pe wọn yoo ṣi wa lọna. Ṣe a wa ni amuyẹ to lati yago fun wọn? Bẹẹni, a ni amuyẹ to lati yago fun wọn ati lati rin ni iṣẹgun lori awọn ẹmi buruku ti wọn n lo wọn. Iwọ naa wo nkan ti Johanu sọ lori eyi:
“Olufẹ, ẹ máṣe gbà gbogbo ẹmí gbọ́, ṣugbọn ẹ dán awọn ẹmí wò bi nwọn ba ṣe ti Ọlọrun: nitori awọn woli eke pupọ̀ ti jade lọ sinu aiye. Eyi li ẹ o fi mọ̀ Ẹmí Ọlọrun: gbogbo ẹmí ti o ba jẹwọ pe, Jesu Kristi wá ninu ara, ti Ọlọrun ni: Gbogbo ẹmí ti kò si jẹwọ pe, Jesu Kristi wá ninu ara, kì iṣe ti Ọlọrun: eyi si li ẹmí Aṣodisi-Kristi na, ti ẹnyin ti gbọ́ pe o mbọ̀, ati nisisiyi o si ti de sinu aiye. Ẹnyin ọmọ mi, ti Ọlọrun li ẹnyin, ẹnyin si ti ṣẹgun wọn: nitori ẹniti mbẹ ninu nyin tobi jù ẹniti mbẹ ninu aiye lọ. Ti aiye ni nwọn, nitorina ni nwọn ṣe nsọrọ bi ẹni ti aiye, aiye si ngbọ́ ti wọn. Ti Ọlọrun li awa: ẹniti o ba mọ̀ Ọlọrun o ngbọ́ ti wa: ẹniti kì ba nṣe ti Ọlọrun kò ngbọ́ ti wa. Nipa eyi li awa mọ̀ ẹmí otitọ, ati ẹmí eke.” (1Jòhánù 4:1-6)
Ki ni ikilọ akọkọ ti a fun wa ninu awọn ẹsẹ bibeli yi? Oun naa ni pe ki a ma ṣe gba gbogbo ẹmi gbọ, ṣugbọn ki a ma a kọkọ dan wọn wo. Eyi n jẹ ki o ye wa pe ko ki i ṣe gbogbo awọn ti wọn n lọ kaakiri ni orukọ Jesu ni wọn jẹ ti Ọlọrun tabi ni wọn n ṣiṣẹ nipasẹ Ẹmi Ọlọrun. Wọn le ma sọ asọtẹlẹ. Wọn le ma ṣiṣe iwosan ati iṣẹ imularada. Wọn le ma ṣe oniruru nkan ni orukọ Jesu. Iyẹn ko tunmọ si pe wọn jẹ ti Jesu tabi wipe Ẹmi rẹ n gbe inu wọn. A ni lati kọkọ dan wọn wo naa, ki a si mọ irufẹ ẹmi ti o n ba wọn ṣiṣẹ ki a to darapọ mọ wọn tabi fi aye gba wọn ninu aye wa.
Ọpọ loni ni wọn ma n sara kunlẹ fun adura tabi isọtẹlẹ niwaju ẹnikẹni ti wọn ba ti sọ wipe wolii ni. O le jẹ nitoripe ẹni naa gba adura ti o n milẹ titi niwaju wọn tabi nitoripe o ṣe awọn iṣẹ iyanu kan loju wọn ni. Ṣugbọn o lodi si ifẹ Ọlọrun lati sare tẹriba fun ẹni ti a ko i ti dan wo lati mọ boya ti Ọlọrun ni tabi ti eṣu ni tabi lati ko aye wa le e lọwọ. Eyi si jẹ ọkan lara awọn idi ti awọn eke wolii ṣe n ri aye ba aye ọpọ eniyan jẹ, ti wọn si tun n ri aye wu igbagbọ wọn ni ewu.
Ki a ma fa ọrọ gun, Johanu n jẹ ki o ye wa pe nkan ti o tọ fun wa ni pe ki a kọkọ dan ẹni yowu ti o ba pe ara rẹ ni iranṣẹ Ọlọrun tabi ọmọ Ọlọrun wo lati mọ boya ti Ọlọrun ni o jẹ nitootọ tabi ti Eṣu. Lọna wo? Bi apọsiteli yi ti ṣe fi han wa, a le dan wọn wo nipa nkan ti wọn gbagbọ nipa Jesu. Ni asiko ti o kọ lẹta yi, bi lẹta naa ti n fi ye wa, o fẹrẹ dabi wipe awọn kan wa ti wọn n polongo Jesu gẹgẹ bi Oluwa wọn ṣugbọn ti wọn ko gba pe O wa sinu aye ninu ara gẹgẹ bi eniyan. Niwọn igba ti wọn ko si gba eyi gbọ, nkan ti wọn n sọ ni pe ko ki i ṣe eniyan ni o ku fun wa bikoṣe ẹmi-ọrun kan. Eyi si lodi si nkan ti a kọ sinu Iwe mimọ ati ti awọn apọsiteli igbaani ri, ti wọn si jẹ ẹlẹri rẹ. Nitorina, wọn n kilọ fun awọn ọmọ Ọlọrun igbaani ati awa naa lati ma tẹle irufẹ awọn onigbagbọ yi.
Eyi wa n jẹ ki o ye wa pe irufẹ nkan ti awọn eniyan gbagbọ nipa Jesu, nipa Ọlọrun ati nipa Ẹmi mimọ ṣe pataki pupọ. Ẹnikẹni ti nkan ti o gbagbọ ba si ti lodi si nkan ti a kọ sinu Iwe mimọ nipa Jesu, Ọlọrun ati Ẹmi mimọ jẹ ẹni ti a gbọdọ kiyesi, ki a si tun yẹra fun. Ẹnikẹni ti ko ba si tun gba gbogbo awọn akọsilẹ awọn apọsiteli igbaani gbọ lori iyinrere Jesu kirisiti ki i ṣe ti Ọlọrun; ti Eṣu ni ẹni naa jẹ. A si gbọdọ yago fun ki ẹmi buburu, ẹmi aṣodi-si-Kirisiti ti o n ba irufẹ ẹni bẹ ṣiṣẹ ma ba ri awa naa tan jẹ tabi ṣi lọna.
Ko ki i wa ṣe nipa ẹkọ eke tabi igbagbọ ti o lodi si Iwe mimọ nikan ni a fi le mọ awọn aṣodi-si-Kirisiti tabi awọn eke Kirisitiẹni. A tun le mọ wọn nipasẹ irufẹ igbe aye ti wọn n gbe. Ti wọn ko ba i ti ma gbe igbe aye ododo ati ifẹ, a ni lati fura si wọn. O ṣeeṣe ki wọn ma jẹ ti Jesu rara. Iwọ naa wo nkan ti Jesu funrarẹ sọ lori eyi:
“Ẹ mã kiyesi awọn eke woli ti o ntọ̀ nyin wá li awọ agutan, ṣugbọn apanijẹ ikõkò ni nwọn ninu. Eso wọn li ẹnyin o fi mọ̀ wọn. Enia a mã ká eso ajara lori ẹgún ọgàn, tabi eso ọpọtọ lara ẹ̀wọn? Gẹgẹ bẹ̃ gbogbo igi rere ni iso eso rere; ṣugbọn igi buburu ni iso eso buburu. Igi rere ko le so eso buburu, bẹ̃ni igi buburu ko si le so eso rere. Gbogbo igi ti ko ba so eso rere, a ké e lùlẹ, a si wọ́ ọ sọ sinu iná. Nitorina nipa eso wọn li ẹnyin o fi mọ̀ wọn. Ki iṣe gbogbo ẹniti npè mi li Oluwa, Oluwa, ni yio wọ ijọba ọrun; bikoṣe ẹniti nṣe ifẹ ti Baba mi ti mbẹ li ọrun. Ọpọlọpọ enia ni yio wi fun mi li ọjọ na pe, Oluwa, Oluwa, awa ko ha sọtẹlẹ li orukọ rẹ? ati orukọ rẹ ki a fi lé awọn ẹmi èṣu jade? ati li orukọ rẹ ki a fi ṣe ọ̀pọ iṣẹ iyanu nla? Nigbana li emi o si wi fun wọn pe, Emi kò mọ̀ nyin ri, ẹ kuro lọdọ mi, ẹnyin oniṣẹ ẹ̀ṣẹ.” (Mátíù 7:15-23)
Njẹ o ri bayẹn? Ko ki i ṣe gbogbo awọn ti o wa ni orukọ Jesu naa ni ti Jesu, ko si ki i ṣe gbogbo awọn ti o n le ẹmi eṣu jade tabi ṣiṣẹ iyanu ni orukọ Jesu naa ni o jẹ tirẹ. Judasi Isikariotu, fun apẹrẹ, ṣe iṣẹ iyanu, o si tun le awọn ẹmi eṣu jade ni orukọ Jesu. Sibẹsibẹ, Jesu pe e ni ọmọ egbe. A si ri ọpọ naa loni ti o jẹ wipe ọmọ egbe ni wọn, bi o tilẹ jẹ wipe a mọ wọn si wolii, alufa, ajinyinrere ati bẹẹbẹẹ lọ.
Iha wo wa ni ki a kọ si irufẹ awọn wọnyi? A gbọdọ yẹra fun wọn ni. Aijẹbẹ, wọn yoo ṣe igbagbọ wa ni ijamba. Bi mo ti wa sọ tẹlẹ, Johanu jẹ ki o ye wa pe Ọlọrun ti ṣe wa yẹ lati rin ni iṣẹgun lori awọn eke wọnyi ati lori awọn ẹmikẹmi, ẹmi aṣodi-si-Kirisiti ti o n ba wọn ṣiṣẹ. Lọna wo? Ẹni ti o ngbe inu wa ju ẹni ti o ngbe inu wọn lọ! Tani o n gbe inu wa? Ẹmi Ọlọrun ni! O si lagbara ju Eṣu ati gbogbo awọn ẹmi buburu rẹ lọ. Nitorina, awa ti ṣẹgun wọn naa. Ti a ko ba si fi aye gba wọn, nṣe ni a o ma a fi ojoojumọ rin ni iṣẹgun lori wọn ati lori awọn iṣẹ buburu wọn.
Lẹyin igba ti o ti wa pe akiyesi wa si awọn nkan wọnyi tan, Johanu pada sori nkan ti o n ba wa sọ tẹlẹ lori rinrin ninu ifẹ. Wo nkan ti o sọ:
“Olufẹ, ẹ jẹ ki a fẹràn ara wa: nitori ifẹ ti ọdọ Ọlọrun wá; ati gbogbo ẹniti o ba ni ifẹ, a bí i nipa ti Ọlọrun, o si mọ̀ Ọlọrun. Ẹniti kò ba ni ifẹ kò mọ̀ Ọlọrun: nitoripe ifẹ ni Ọlọrun. Nipa eyi li a gbé fi ifẹ Ọlọrun hàn ninu wa, nitoriti Ọlọrun rán Ọmọ bíbi rẹ̀ nikanṣoṣo si aiye, ki awa ki o le yè nipasẹ rẹ̀. Ninu eyi ni ifẹ wà, kì iṣe pe awa fẹ Ọlọrun, ṣugbọn on fẹ wa, o si rán Ọmọ rẹ̀ lati jẹ ètutu fun ẹ̀ṣẹ wa. Olufẹ, bi Ọlọrun ba fẹ wa bayi, o yẹ ki a fẹràn ara wa pẹlu. Ẹnikẹni kò ri Ọlọrun nigba kan ri. Bi awa ba fẹràn ara wa, Ọlọrun ngbé inu wa, a si mu ifẹ rẹ̀ pé ninu wa. Nipa eyi li awa mọ̀ pe awa ngbé inu rẹ̀, ati on ninu wa, nitoriti o ti fi Ẹmí rẹ̀ fun wa. Awa ti ri, a si jẹri, pe Baba rán Ọmọ rẹ̀ lati jẹ́ Olugbala fun araiye. Ẹnikẹni ti o ba jẹwọ pe Jesu Ọmọ Ọlọrun ni, Ọlọrun ngbé inu rẹ̀, ati on ninu Ọlọrun.” (1Jòhánù 4:7-15)
Ki ni Johanu sọ wipe ki a ṣe o? O ni ki a fẹran ara wa. Ki ni idi? Idi ni pe ọdọ Ọlọrun ni ifẹ ti wa. Iyẹn tunmọ si pe Ọlọrun ni orisun ifẹ, iyẹn ifẹ aiṣẹtan. O si ti wa fi ifẹ ran han si wa nipa fifi ọmọ rẹ silẹ gẹgẹ bi etutu fun ẹṣẹ wa. O tun fi ifẹ rẹ han si wa nipa pe ko duro de igba ti a ba fẹran rẹ ki O to fẹran wa. Ko si tun duro de igba ti iwa wa ba suwọn, ti o si ba ifẹ rẹ mu ki O to fẹran wa lati gba wa la. Dipo eyi, ninu ẹṣẹ wa, ninu aiṣedede wa, O fi ifẹ han si wa nipa fifa ọmọ rẹ kalẹ lati ra wa pada. (Wo: Róòmù 5:8)
Niwọn igba ti Ọlọrun wa fi ifẹ rẹ si wa han ni ọna yi, o yẹ ki awa naa ma a fi ifẹ han si awọn ara wa ninu Kirisiti ati awọn ti o wa ni awujọ wa. Ti a ko ba si ma a ṣe eyi, nṣe ni a n tan ara wa jẹ. A jẹ wipe a ko i ti ba Ọlọrun pade niyẹn. Bi Johanu tun ṣe jẹ ki o ye wa, ko si ẹnikẹni ti o ti fi oju ri Ọlọrun ri. Lotitọ, oniruuru eniyan ni o ti ri ifarahan Ọlọrun. Amọ, ko i ti si ẹnikẹni ti o ri Ọlọrun ri ninu gbogbo ogo ati ẹwa rẹ. Ẹni ti o ba ri eyi di dandan ki o ku, bi Ọlọrun ti ṣe sọ fun Mose. Idi si ni pe ẹran ara wa yi ko le ri ogo Ọlọrun ki o si ye. Abalajọ ti a fi sọ fun wa pe a o yi agọ ara wa pada nigba ti Jesu ba pada wa lati mu wa wa si ọdọ Ọlọrun. (Wo: Ẹ́kísódù 33:18-23; 1Kọ́ríntì 15:50-54; Fílípì 3:20-21)
Amọ ṣa o, bi o tilẹ jẹ wipe ko si ẹnikẹni ti o ti ri Ọlọrun ri, ẹnikẹni ti o ba n rin ninu ifẹ n fi han pe Ọlọrun n gbe inu oun ati wipe oun mọ ọn. Bawo si ni eyi ṣe ṣeeṣe? O ṣeeṣe nipa Ẹmi Ọlọrun ti o n gbe inu wa. Nkan ti a n sọ nipe a mọ wipe Ẹmi mimọ ti o n gbe inu awa ti a gba Jesu gbọ ni O ma n jẹ ki a mọ Ọlọrun daju ati ki a ni iriri Ẹni ti Ọlọrun jẹ. Ẹmi yi kanna si tun ni O n jẹ ki o ṣeeṣe fun wa lati rin ninu ifẹ gẹgẹ bi Ọlọrun. Eyi si wa ni ibamu pẹlu nkan ti Pọọlu sọ fun wa ninu lẹta rẹ pe: “Ireti kì si idojuti ni; nitori a ti tan ifẹ Ọlọrun ká wa lọ́kàn lati ọdọ Ẹmí Mimọ́ wá ti a fifun wa.” (Róòmù 5:5)
Njẹ o ri bayẹn? Nipasẹ Ẹmi Ọlọrun ni a n gba kun ọkan wa pẹlu ifẹ. Eyi tunmọ si pe ko si ẹnikẹni ti o le rin ninu ifẹ otitọ ati ifẹ ti o peye ti ko ba ṣe pe Ẹmi Ọlọrun fun ni okun lati ṣe bẹ ẹ. Ara idi si ni yi ti Johanu ṣe n tẹnumọ pe ko si ẹni ti o jẹ ti Ọlọrun nitootọ ti ko ni ma rin ninu ifẹ. Yoo ma a rin ninu ifẹ nitoripe Ẹmi Ọlọrun n gbe inu rẹ. Ẹmi yi yoo si ma a fun ni okun lati rin ninu ifẹ.
Siwaju si, Johanu tun sọ awọn nkan wọnyi fun wa lori ifẹ ati bi a ti ṣe n fi i han:
“Awa ti mọ̀, a si gbà ifẹ ti Ọlọrun ní si wa gbọ́. Ifẹ ni Ọlọrun; ẹniti o ba si ngbé inu ifẹ o ngbé inu Ọlọrun, ati Ọlọrun ninu rẹ̀. Ninu eyi li a mu ifẹ ti o wà ninu wa pé, ki awa ki o le ni igboiya li ọjọ idajọ: nitoripe bi on ti ri, bẹ̃li awa si ri li aiye yi. Ìbẹru kò si ninu ifẹ; ṣugbọn ifẹ ti o pé nlé ibẹru jade: nitoriti ìbẹru ni iyà ninu. Ẹniti o bẹ̀ru kò pé ninu ifẹ. Awa fẹran rẹ̀ nitori on li o kọ́ fẹran wa. Bi ẹnikẹni ba wipe, Emi fẹran Ọlọrun, ti o si korira arakunrin rẹ̀, eke ni: nitori ẹniti kò fẹran arakunrin rẹ̀ ti o ri, bawo ni yio ti ṣe le fẹran Ọlọrun ti on kò ri? Ofin yi li awa si ri gbà lati ọwọ́ rẹ̀ wá, pe ẹniti o ba fẹran Ọlọrun ki o fẹran arakunrin rẹ̀ pẹlu.” (1Jòhánù 4:16-21)
Lara awọn nkan ti Johanu fẹ ki a tun di mu ninu lẹta yi ni pe ifẹ ni Ọlọrun funrarẹ. A wa ni lati ni igbagbọ ninu ifẹ ti Ọlọrun ni si wa lati le jẹ igbadun rẹ. Ti a ko ba ni igbagbọ ninu ifẹ eniyan si wa, a ko le ṣe amulo ifẹ ẹni naa si wa bi o ti ṣe tọ ati yẹ, ki a si tun jẹ igbadun rẹ. Bẹẹ gẹgẹ naa ni o si ri pẹlu ibaṣepọ wa pẹlu Ọlọrun. Ti a ko ba gbagbọ ninu ifẹ rẹ si wa, a ko ni fi aye wa ati ara wa jin fun lati mojuto. Yatọ si eyi, awa funrawa ko ni rin ninu ifẹ si ọmọnikeji wa. Idi ni yi ti o fi ma n nira lati ba awọn ti iya ifẹ ba ti jẹ ṣe pọ. Irufẹ awọn wọnyi ko ki i gbagbọ ninu ifẹ. Nitorina, bi ẹ tilẹ n fi ifẹ han wọn, nṣe ni yoo ma jọ wọn loju, ti yoo si da bi ẹni pe ẹ n dọgbọn lati rẹ wọn jẹ ni. Ṣugbọn awọn ti o ba gbagbọ ninu ifẹ ma n tete yọ mọ ẹni ti o ba fẹ wọn ati lati fi ifẹ han pada si ẹni naa.
Wayi o, niwọn igba ti Ọlọrun ti fi ifẹ han wa, a ni lati gbagbọ ninu ifẹ rẹ, ki awa naa si ma fi ifẹ wa han si nipa fifi ifẹ han si awọn ti o wa ni ayika wa. Niwọn igba ti a ba si gbagbọ ninu ifẹ rẹ, ẹru ko ni ba wa lati pade rẹ ni ọjọ idajọ. Ṣaaju ninu lẹta yi, Johanu ti sọ fun wa pe ti a ba tẹsiwaju lati ma gbe ninu Kirisiti nipa gbigba ọrọ rẹ laye ninu ọkan wa, ẹru ko ni ba wa lati pade rẹ ni ọjọ idajọ (1Jòhánù 2:28). O tun wa n sọ fun wa bayi pe ti a ba n rin ninu ifẹ rẹ, ẹru ko ni ba wa lati pade rẹ ni ọjọ idajọ. Nitoripe ko si ibẹru ninu ifẹ ti o peye, ifẹ otitọ. Ibi ti ko ba ti si ifẹ ni ẹru ti ma n ba awọn eniyan.
Amọ ifẹ wa ninu wa nitoripe Ọlọrun ni o kọkọ fi ifẹ han wa. O si ti wa ṣe wa yẹ gẹgẹ bi O ti ṣe Jesu yẹ. Nitorina, bi Jesu ti ṣe jẹ ojulowọ ọmọ niwaju rẹ ni awa naa ṣe je ojulowo ọmọ niwaju rẹ. Iyẹn jasi pe irufẹ ifẹ kan naa ni O ni si wa. Eyi ma ga o!
Ọ̀RỌ̀ ÍPARÍ
Ni akotan, Johanu jẹ ki o ye wa pe Ọlọrun ni orisun ifẹ wa. Oun ni o kọkọ fẹran wa, ti O si fa wa sọdọ gẹgẹ bi ọmọ. Ti a ba wa sọ wipe a fẹran rẹ, iyẹn ẹni ti a ko ri, amọ ti a korira awọn ara wa ti a le e ri, nṣe ni a n tan ara wa jẹ. Idi si niyi ti o fi jẹ wipe ofin kan ṣoṣo ti Ọlọrun fun wa ni pe ẹnikẹni ti o ba sọ wipe oun fẹran Oun gbọdọ fẹran arakunrin rẹ pẹlu.
ÌBEÈRÈ
– Gbogbo ẹmi ki i ṣe ti Ọlọrun. Ki ni iha ti Kirisitiẹni yẹ ki o kọ si eyi.
– Ọna wo ni Ọlọrun gba jẹ orisun ifẹ?
Láti ọ́wọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2025 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)
ÀKỌ́RÍ: 1JÒHÁNÙ 3-ỌMỌ ỌLỌ́RUN TÀBÍ ỌMỌ ÈṢÙ | ÀYỌKÀ: 1JÒHÁNÙ 3:1-24 | ỌJỌ́RÚ 13, ÒGÚN 2025
ÀKỌ́SÓRÍ: “Ẹniti o ba ndẹṣẹ ti Èṣu ni; nitori lati àtetekọṣe ni Èṣu ti ndẹṣẹ. Nitori eyi li Ọmọ Ọlọrun ṣe farahàn, ki o le pa iṣẹ Èṣu run.” (1Jòhánù 3:8)
Ọ̀RỌ̀ ÌSÀÁJÚ
Ni ori ikeji lẹta Johanu ti a n gbeyẹwo yi, o jẹ ki o ye wa pe o ṣeeṣe ki eniyan ma tan ara rẹ jẹ, ki o si ro wipe oun n ba Ọlọrun rin. Ẹni ti o ba n ba Ọlọrun rin yoo fi han ninu iwuwasi rẹ. Nitorina, ẹnikẹni ti iwuwasi rẹ ko ba ti jọ ti Ọlọrun kan n tan ara rẹ jẹ ni, bi o tilẹ sọ wipe ọmọ Ọlọrun ni oun. Johanu, ni ori ikẹta lẹta naa, tun wa pada si ori ọrọ yi lati jẹ ki a mọ pe iyatọ kedere wa laarin awọn ti o jẹ ọmọ Ọlọrun ati awọn ti o jẹ ọmọ Eṣu. O tilẹ fẹ ki o ye wa pe oriṣi eniyan meji pere ni o wa laye – awọn ọmọ Ọlọrun ati awọn ọmọ Eṣu. Ewo wa ni a wa jẹ? Johanu dahun ibere yi ninu ori ikẹta naa. Njẹ ki Ọlọrun fi oye idahun rẹ ye wa, ki O si tun fun wa ni okun lati kọ iha ti o tọ si i. Amin.
ỌMỌ ỌLỌ́RUN TÀBÍ ỌMỌ ÈṢÙ
Wayi o, nkan akọkọ ti Johanu jẹ ki o ye wa ni ori ikẹta lẹta yi ni pe ojulowo ọmọ Ọlọrun ni gbogbo awa ti a gba Jesu gẹgẹ bi Kirisiti jẹ. Eyi jasi pe Ọlọrun ti tun wa bi nitootọ ninu ọkan wa, O si ti sọ wa di tirẹ. Wo bi o ti ṣe gbe ọrọ naa kalẹ:
“Ẹ wo irú ifẹ ti Baba fi fẹ wa, ti a fi npè wa ni ọmọ Ọlọrun; bẹ̃ li a sa jẹ. Nitori eyi li aiye kò ṣe mọ̀ wa, nitoriti ko mọ̀ ọ. Olufẹ, ọmọ Ọlọrun li awa iṣe nisisiyi, a kò si ti ifihàn bi awa ó ti ri: awa mọ pe, nigbati a bá fihan, a ó dabi rẹ̀; nitori awa o ri i ani bi on ti ri. Olukuluku ẹniti o ba si ni ireti yi ninu rẹ̀, a wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́, ani bi on ti mọ́.” (1Jòhánù 3:1-3)
Ki ni o jẹ ki Ọlọrun sọ wa di ọmọ rẹ? Ifẹ ni! Eniyan ti ṣẹ, o si ti kuna ogo Ọlọrun. Nitorina, idajọ iku ayeraye nikan ti o tọ si wa. Amọ nitori ifẹ rẹ ti o ga, Ọlọrun ṣaanu fun wa, O san gbese ẹṣẹ wa, O si fi aaye silẹ fun wa lati di ọmọ rẹ. Ẹnikẹni ti o ba si wa gba Jesu gbọ ti di ọmọ Ọlọrun lotitọ. (Wo: Róòmù 3:23-26; Éfésù 2:1-10)
Wayi o, nkan ẹmi ni a n sọrọ nipa nibiyi, ko ki i ṣe nkan ti ara. Nitorina, awọn ti aye yi ti oye nkan ẹmi ko ye ko le ri wa gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun. Nkan ti a n sọ ko tilẹ le ni itumọ si wọn. Ko si le ni itumọ si wọn nitoripe didi ọmọ Ọlọrun lọna yi ko ni mu iyipada ba agọ ara eniyan ti a n gbe kaakiri. Agọ ara kanna si ni a o ma gbe kaakiri titi Jesu yoo fi de lati wa mu wa sọdọ rẹ. Amọ nigba ti O ba de, irufẹ agọ ara yowu ti O ba ni ni awa naa yoo ni. Gbogbo awa ti ba si n pongbẹ fun eyi yoo ri daju wipe a wẹ ara wa mọ kuro ninu ohun gbogbo ti o n jẹ idibajẹ ninu aye yi. (Wo: Fílípì 3:20-21)
Nkan ti a n sọ ni wipe, ẹnikẹni ti o ba ri ara rẹ gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun yoo ma a fi oju sọna fun bibọ Jesu. Ti o ba si n foju sọna fun bibọ rẹ, yoo tun ma a lepa lati ri wipe oun wa ni mimọ ati ni ailabawọn nigba ti o ba de. Eyi ni yoo jẹ ki o le pade rẹ pẹlu igboya, gẹgẹ bi Johanu ti sọ siwaju ni ori ikeji lẹta yi (1Jòhánù 2:28).
Ẹni ti ko ba wa ṣe eleyi, ti ko ma fi igba gbogbo wa ni imurasilẹ de bibọ Jesu nipa wiwẹ ara rẹ mọ kuro ninu awọn idibajẹ aye yi, ko le sọ daju-ṣaka pe ọmọ Ọlọrun ni oun. Bi o ba tilẹ jẹ ọmọ Ọlọrun ni nitootọ, o ti n fi aye silẹ fun awọn eniyan lati ṣiyemeji lori ọrọ rẹ. Ki ni idi? Gẹgẹ bi Johanu ti fi ye wa ni ori ikẹta lẹta yi, idi ni wipe awọn ọmọ Eṣu ni wọn ma n fi ara wọn jin fun ẹṣẹ dida. Wọn a si ma fi ara wọn jin fun ẹṣẹ dida nitoripe ẹlẹṣẹ ni baba wọn, iyẹn Eṣu. Ki a wa ba a le bọ lọwọ Eṣu ati ẹṣẹ ni Ọlọrun ṣe fa ọmọ rẹ kalẹ gẹgẹ bi etutu fun ẹṣẹ wa. Ṣe o tun wa yẹ ki a sọ wipe a ti bọ lọwọ ẹṣẹ, ki a si tun ma gbe ninu rẹ? Ko yẹ!
Nitorina, Johanu tẹsiwaju lati sọ awọn nkan wọnyi fun wa lori oju ti a fi gbọdọ wo ẹṣẹ:
“Ẹnikẹni ti o ba ndẹṣẹ o nrú ofin pẹlu: nitori ẹ̀ṣẹ ni riru ofin. Ẹnyin si mọ̀ pe, on farahàn lati mu ẹ̀ṣẹ kuro; ẹ̀ṣẹ kò si si ninu rẹ̀. Ẹnikẹni ti o ba ngbé inu rẹ̀ ki idẹṣẹ; ẹnikẹni ti o ba ndẹṣẹ kò ri i, bẹ̃ni kò mọ̀ ọ. Ẹnyin ọmọ mi, ẹ máṣe jẹ ki ẹnikẹni ki o tàn nyin: ẹniti o ba nṣe ododo, o jasi olododo, gẹgẹ bi on ti iṣe olododo. Ẹniti o ba ndẹṣẹ ti Èṣu ni; nitori lati àtetekọṣe ni Èṣu ti ndẹṣẹ. Nitori eyi li Ọmọ Ọlọrun ṣe farahàn, ki o le pa iṣẹ Èṣu run. Ẹnikẹni ti a ti ipa Ọlọrun bí, ki idẹṣẹ; nitoriti irú rẹ̀ ngbe inu rẹ̀: kò si le dẹṣẹ nitoripe a ti ti ipa Ọlọrun bi i. Ninu eyi li awọn ọmọ Ọlọrun nfarahan, ati awọn ọmọ Èṣu: ẹnikẹni ti kò ba nṣe ododo kì iṣe ti Ọlọrun, ati ẹniti kò fẹràn arakunrin rẹ̀.” (1Jòhánù 3:4-10)
Ki ni ẹṣẹ? Riru ofin Ọlọrun ni! Ki wa ni idi ti Jesu ṣe farahan? O farahan lati yanju ẹṣẹ. O si le ṣe eyi nitoripe ẹṣẹ ko si ninu rẹ. Awa ti a ba wa n gbe inu rẹ ko le fi ara wa jin fun ẹṣẹ. Ẹni ti o ba sọ wipe oun n gbe inu rẹ, ti o si tun gbe igbe aye ẹṣẹ ko i ti mọ ọn rara. O kan n tan ara rẹ jẹ ni.
Ki ni idi? Bi mo ti ṣe sọ siwaju, idi ni wipe Eṣu ni orisun ẹṣẹ, nigbati Jesu si jẹ orisun ododo. Ẹni ti o ba wa n dẹṣẹ n fi han wipe ọmọ Eṣu ni oun – oun ko ki i ṣe ọmọ Ọlọrun. Jesu ti wa lati mu ẹṣẹ wa kuro ati lati pa orisun rẹ run ninu aye wa. Ti a ba si wa jẹ tirẹ nitootọ, a o ri wipe oriṣun ẹṣẹ ko si ninu aye wa mọ. Nitorina a ko ni fi ara wa jin fun igbe aye ẹṣẹ dida. A ko ni fi ara wa jin fun ẹṣẹ dida nitoripe Ọlọrun ti tun wa bi, O si ti fi irugbin iye ati ododo rẹ sinu aye wa. Nitorina, oriṣun wa ti yipada. Iye ati ododo ni orisun naa yoo ma mu jade dipo iku ati ẹṣẹ.
Ṣe o wa ri idi ti Johanu fi pin gbogbo eniyan si isọri meji bayi? O pe awọn kan ni ọmọ Ọlọrun. O si pe awọn yoku ni ọmọ Eṣu. Idi ni wipe Ọlọrun ati Eṣu naa ni orisun meji ti o wa. Ẹni ti a ba si jẹ tirẹ ni yoo sọ irufẹ orisun aye wa ati awọn nkan ti yoo ma sun, yala ẹṣẹ tabi ododo. A le ma ti oju wa mọ boya ti Ọlọrun ni a jẹ tabi ti Eṣu. Ṣugbọn nkan ti aye wa ba n sun jade, yala ẹsẹ tabi ododo, ni yoo sọ eyi ti n ṣe okodoro lori ọrọ naa.
Njẹ awọn nkan ti Johanu n sọ yi wa tumọ si pe ọmọ Ọlọrun ko le e dẹṣẹ rara? Ti a ba wo ẹsẹ ikẹsan ori ikẹta yi, o fẹrẹ dabi ẹni wipe nkan ti Johanu n sọ gan-an niyẹn. Ṣugbọn ti a ba tun wo awọn nkan ti o ti sọ sẹyin ninu lẹta kanna, a o ri wipe ko ṣeeṣe ki o ma a sọ wipe ẹni ti o ba ti di ọmọ Ọlọrun ko le dẹsẹ rara. Lotitọ, ko yẹ ki ọmọ Ọlọrun dẹṣẹ rara, nitoripe ko si irugbin ẹṣẹ ninu aye rẹ. Amọ bi Ọlọrun ti ṣe fi irugbin rẹ sinu aye rẹ ni Eṣu naa n lepa lati fi irugbin ẹṣẹ sinu aye rẹ. Ti ko ba si wa kiyesara to, Eṣu le ṣe aṣeyọri lati fun awọn irugbin idibajẹ kan sinu aye rẹ. O si di dandan ki o so eso awọn irugbin idibajẹ naa, ti ko ba tete fa wọn tu. Idi si niyi ti Johanu fi jẹ ki o ye wa pe idariji wa fun ọmọ Ọlọrun ti o ba dẹṣẹ, ti o ba si jẹwọ rẹ. (Wo: 1Jòhánù 1:8-10)
Koko nkan ti a n sọ naa ni pe erongba Johanu ninu lẹta yi kọ ni lati jẹ ki a ro wipe ọmọ Ọlọrun ko le dẹṣẹ rara. Dipo bẹ ẹ, erongba rẹ ni lati jẹ ki a mọ wipe ẹni ti o ba jẹ ọmọ Ọlọrun nitootọ ko ni fẹ lati ma dẹṣẹ tabi gbe ninu ẹṣẹ. Idi si ni pe a ti tun bi, irugbin Ọlọrun si n bẹ ninu aye rẹ. Nitorina, ko ṣeeṣe fun lati tẹsiwaju lati ma dẹṣẹ.
Johanu wa tẹsiwaju lati jẹ ki o ye wa si i pe ọna kan pataki lati fi han pe a jẹ ọmọ Ọlọrun nitootọ ni ki a ma rin ninu ifẹ. Nipasẹ ifẹ ni Ọlọrun fi tun wa bi, ti O si da wa lare. Ti a ba wa jẹ tirẹ nitootọ, awa naa gbọdọ ma fi igba gbogbo rin ninu ifẹ. Eyi si gbọdọ kọja ọrọ ẹnu – o gbọdọ han ninu iwuwasi ati iṣeṣi wa. Wo awọn nkan ti o sọ lori ọrọ naa:
“Nitori eyi ni iṣẹ ti ẹnyin ti gbọ́ li àtetekọṣe, ki awa ki o fẹràn ara wa. Ki iṣe bi Kaini, ti jẹ́ ti ẹni buburu nì, ti o si pa arakunrin rẹ̀. Nitori kili o si ṣe pa a? Nitoriti iṣẹ on jẹ buburu, ti arakunrin rẹ̀ si jẹ ododo. Ki ẹnu ki o máṣe yà nyin, ẹnyin ará mi, bi aiye ba korira nyin. Awa mọ̀ pe awa ti rekọja lati inu ikú sinu ìye, nitoriti awa fẹràn awọn ará. Ẹniti kò ba ni ifẹ o ngbé inu ikú. Ẹnikẹni ti o ba korira arakunrin rẹ̀ apania ni: ẹnyin si mọ̀ pe kò si apania ti o ni ìye ainipẹkun lati mã gbé inu rẹ̀. Nipa eyi li awa mọ̀ ifẹ nitoriti o fi ẹmí rẹ̀ lelẹ fun wa: o si yẹ ki awa fi ẹmí wa lelẹ fun awọn ará. Ṣugbọn ẹniti o ba ni ohun ini aiye, ti o si ri arakunrin rẹ̀ ti iṣe alaini, ti o si sé ilẹkun ìyọ́nu rẹ̀ mọ ọ, bawo ni ifẹ Ọlọrun ti ngbé inu rẹ̀? Ẹnyin ọmọ mi, ẹ máṣe jẹ ki a fi ọrọ tabi ahọn fẹran, bikoṣe ni iṣe ati li otitọ.” (1Jòhánù 3:11-18)
Njẹ o ri bayi? Ririn ninu ifẹ ni nkan akọkọ ti yoo fi han wipe ti Ọlọrun ni a jẹ. Johanu si lo Kaini, ọmọ akọkọ ti Adamu bi, lati ṣe apẹrẹ fun wa nkan ti o n sọrọ nipa. Kaini pa arakunrin rẹ Abẹli. Ki ni idi? Idi ni wipe ọmọ Eṣu ni. Lotitọ, oun naa mu ẹbọ wa fun Ọlọrun gẹgẹ bi arakunrin rẹ Abẹli ti ṣe ṣe. Amọ, Ọlọrun ko tẹwọgba ẹbọ rẹ. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 4:1-8)
A ko wa mẹnuba idi ti Ọlọrun ko fi tẹwọgba ẹbọ Kaini fun wa ninu iwe Jẹnẹsisi. Nitori eyi, ọpọ ni o ro wipe Ọlọrun ko tẹwọgba ẹbọ rẹ nitoripe irugbin ti ko dara ni o mu wa fun un. Awọn miran, ẹwẹ, ro wipe Ọlọrun ko tẹwọgba ẹbọ rẹ nitoripe ko ki i ṣe nkan ẹlẹ́jẹ̀ ni o fi rubọ. Ṣugbọn atamọ awọn eniyan ni awọn nkan wọnyi – bibeli kọ ni o sọ wọn.
Gẹgẹ bi a ti ṣe ri ni ori ikẹta iwe Johanu yi, idi ti Ọlọrun ko ṣe gba ẹbọ Kaini ni wipe oniṣẹ ibi ni. Iyẹn jasi pe iṣẹ ọwọ rẹ ko fi igba kankan dara. Nitorina, Ọlọrun ko tẹwọgba aye rẹ, debi wipe yoo wa tẹwọgba ọrẹ rẹ. Oun ti ro wipe oun le fi ọrẹ tu Ọlọrun loju tabi wipe ọrẹ ohun le dipo iwa ododo niwaju Ọlọrun. Ṣugbọn a ko le fi ọrẹ wa tabi adura gbigba tabi ohun miran yowu ti a le ṣe fun Ọlọrun rọpo iwa ododo. Ti a ba jẹ tirẹ, a ko ni ma wa arọpo fun iwa ododo; nṣe ni a o fi ara wa jin fi iwa ododo. Aijẹbẹ, ko ni pẹ ti a o fi fi ara wa han bi Kaini, apaniyan.
Kaini pada fi ara rẹ han bi apaniyan nitoripe ko si ifẹ Ọlọrun ninu rẹ. Nitorina, ẹnikẹni ti ifẹ Ọlọrun ko ba si ninu rẹ, yoo pada fi ara rẹ han gẹgẹ bi apaniyan, bi o tilẹ n pariwo kaakiri pe Jesu ni Oluwa. Ranti wipe Judasi naa pada fi ara rẹ han gẹgẹ bi apaniyan. Nitorina, ẹnikẹni ti ko ba ti fi ifẹ Ọlọrun han ninu igbe aye rẹ ko ki i ṣe ti Ọlọrun, bi O tilẹ n fun ni ọrẹ, waasu tabi ṣe iṣẹ iwosan ni orukọ Jesu. Amọ awọn ti o ba n fi ifẹ rẹ han ninu aye wọn n fihan wipe a ti mu wọn kuro ni ipo iku sinu iye ayeraye.
Koko nkan ti a n sọ naa ni pe jijẹ ọmọ Ọlọrun kọja ọrọ ẹnu. O gbọdọ han ninu iṣesi wa si awọn ara wa ninu Kirisiti ati awọn ti o wa ni awujọ wa. A ko le ma wuwa ọdaju ti ba jẹ ti Ọlọrun nitootọ. Eyi ko fi han wipe tirẹ ni a jẹ. Nṣe ni o n fi han wipe a n tan ara wa jẹ ni.
Johanu wa pari ọrọ rẹ nipa sisọ eyi:
“Ati nipa eyi li awa ó mọ̀ pe awa jẹ ti otitọ, ati pe awa o si dá ara wa loju niwaju rẹ̀. Ninu ohunkohun ti ọkàn wa ba ndá wa lẹbi; nitoripe Ọlọrun tobi jù ọkàn wa lọ, o si mọ̀ ohun gbogbo. Olufẹ, bi ọkàn wa kò ba dá wa lẹbi, njẹ awa ni igboiya niwaju Ọlọrun. Ati ohunkohun ti awa ba bère, awa nri gbà lọdọ rẹ̀, nitoriti awa npa ofin rẹ̀ mọ́, awa si nṣe nkan wọnni ti o dara loju rẹ̀. Eyi si li ofin rẹ̀, pe ki awa ki o gbà orukọ Jesu Kristi Ọmọ rẹ̀ gbọ́, ki a si fẹràn ara wa, gẹgẹ bi o ti fi ofin fun wa. Ẹniti o ba si pa ofin rẹ̀ mọ́ ngbé inu rẹ̀, ati on ninu rẹ̀. Ati nipa eyi li awa mọ̀ pe o ngbé inu wa, nipa Ẹmí ti o fifun wa.” (1Jòhánù 3:19-24)
Ki ni nkan ti apọsiteli yi fẹ ki o ye wa nibiyi? Oun naa ni pe niwọn igba ti a ba n rin ninu ifẹ, a le ni idaniloju niwaju Ọlọrun wipe a n ṣe ifẹ rẹ. Lotitọ, o ṣeeṣe ki ẹri-ọkan wa da wa lẹbi lori awọn nkankan. Amọ niwọn igba ti a ba ti n rin ninu ifẹ ati ni ibamu pẹlu ọrọ Ọlọrun, a ko nilo lati kọbiara si idalẹbi ẹri-ọkan wa. Nṣe ni ki a tẹwọgba nkan ti Ọlọrun n sọ, ki a si ma a rin ninu idalare rẹ. Idi si ni pe Ọlọrun tobi ju ẹri-ọkan wa lọ. Ẹri-ọkan wa si kọ ni onidajọ aye wa; Ọlọrun ni.
Nitorina, nkan ti Ọlọrun ba sọ lori aye wa ni otitọ, yala o dun mọ ẹri-ọkan wa ninu tabi ko dun mọ ninu. Ki a tilẹ sọ otitọ, pe ẹri-ọkan wa da wa lare ko tunmọ si wipe nkan ti a n ṣe wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun. Ara idi ni yi ti Pọọlu fi sọ wipe, “Nitoriti emi kò mọ̀ ohunkohun si ara mi; ṣugbọn a kò ti ipa eyi dá mi lare: Ṣugbọn ẹniti nṣe idajọ mi li Oluwa.” (1Kọ́ríntì 4:4) Ṣe o ri bayẹn?
Amọ ṣa o, ọpọ igba ni ẹri-ọkan wa yoo ma sọ nkan ti o wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun fun wa. Niwọn igba ti ko ba si da wa lẹbi, Johanu sọ wipe a le fi igboya gbadura si Ọlọrun, ki a si ri idahun si adura wa gba. Ṣugbọn a ko gbọdọ ro wipe igboya ti a fi gbadura ni yoo jẹ ki Ọlọrun da wa lohun. Rara O!
Lotitọ, a gbọdọ kọ lati ma fi igboya gbadura si Ọlọrun nitoripe ọmọ rẹ ni a jẹ. Yatọ si iyẹn, Oun funrarẹ gan ti sọ fun wa pe ki a ma fi igboya sunmọ ibi itẹ Oun lati gba ohun yowu ti a ba fẹ (Hébérù 4:16). Amọ nkan ti yoo jẹ ki a ri idahun gba ni pe ki a ma a rin ninu ifẹ rẹ ati ki a ma a gbadura ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ. Ki si ni ifẹ rẹ? Ki a ma gbe igbe aye ifẹ ni ifẹ rẹ fun wa. Awa ti a ba si n ṣe eyi n gbe ninu rẹ, gẹgẹ bi Oun naa ti n gbe inu wa. A si le mọ eyi ninu ọkan wa nipasẹ Ẹmi mimọ rẹ ti o n gbe inu wa.
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Jijẹ ọmọ Ọlọrun ko ki i ṣe ọrọ afẹnusọ lasan. O gbọdọ han ninu iwa ati iṣesi wa. Aijẹbẹ, nṣe ni a kan n tan ara wa jẹ.
ÌBÉÈRÈ
– Ki ni aridaju pe ọmọ Ọlọrun ni a jẹ?
– Ki ni o ṣe pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi?
Láti ọwọ́ Johnson O. Lawal
Copyright © 2025 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)
ÀKỌ́RÍ: 1JÒHÁNÙ 2-ÌTANRAẸNIJẸ | ÀYỌKÀ: 1JÒHÁNÙ 2:1-29 | ỌJỌ́RÚ 09, AGẸMỌ 2025
ÀKỌ́SÓRÍ: “Eyi si ni iṣẹ ti awa ti gbọ lẹnu rẹ ti awa si n jẹ fun yin: pe imọlẹ ni Ọlọrun; ni ọdọ rẹ ko si okunkun rara.” (1Jòhánù 1:5)
Ọ̀RỌ̀ ÌSÀÁJÚ
Ninu ori kinni lẹta akọkọ Johanu ti a n gbe yẹwo, a ri wipe imọlẹ ni Ọlọrun, ko si si okunkun ninu rẹ rara. Eyi wa jasi pe, ẹnikẹni ti o ba sọ wipe oun ni ajọsepọ pẹlu Ọlọrun tabi pe oun n ba a rin gbọdọ ma a rin ninu imọlẹ ọrọ rẹ. Aijẹbẹ, nṣe ni iru ẹni bẹ n tan ara rẹ jẹ. Eyi wa ni Johanu tẹsiwaju lati fi idi rẹ mulẹ ni ori ikeji lẹta naa. Gẹgẹ bi o si ṣe jẹ ki o ye wa, wipe eniyan n ba Ọlọrun rin ko tumọ si pe ko le dẹṣẹ tabi ṣe aṣiṣe. O le dẹṣẹ. O si le ṣe aṣiṣe. Amọ iha ti o ba kọ si ẹṣẹ tabi aṣiṣe rẹ lẹyin igba ti Ọlọrun ba ti tan imọlẹ si ni yoo sọ boya o n ba Ọlọrun imọlẹ rin nitootọ tabi ko ṣe bẹ ẹ. Awọn nkan wọnyi si ni Johanu n fi idi wọn mulẹ fun wa ni ori keji lẹta yi ti a fẹ gbe yẹwo. O n jẹ ki o ye pe eniyan le ma tan ara rẹ jẹ, ki o si ro wipe oun n ba Ọlọrun rin. Bawo wa ni yoo ṣe mọ boya oun n tan ara oun jẹ tabi bẹẹ kọ? Nipa wiwo irufẹ igbe aye ti o n gbe ni.
ÌTANRAẸNIJẸ
Wayi o, irufẹ igbe aye wo ni o yẹ ki ẹni ti ba sọ wipe oun mọ Jesu gbọdọ ma a gbe? Akọkọ, Johanu pe ni igbe aye ailẹṣẹ! Ṣugbọn ṣebi o ti kọkọ jẹ ki o ye wa ni ori ikinni lẹta naa pe o ṣeeṣe ki Kirisitiẹni dẹsẹ tabi ṣe aṣiṣe. Bẹẹni, o ṣeeṣe. Lotitọ, Kirisitiẹni le dẹṣẹ. Ti o ba wa dẹṣẹ, ti o si jẹwọ rẹ, o di dandan ki Ọlọrun dari ẹṣẹ naa ji i, ki O si tun wẹ ẹ mọ kuro ninu aiṣedede rẹ gbogbo. Amọ ko pọn dandan ki Kirisitiẹni dẹṣẹ. Idi si ni pe a ti tun bi, bi a o ti ṣe ri nigba ti a bẹrẹ si ni wo ori ikẹta lẹta yi. Wa a wo nkan ti Johanu sọ lori eyi ni ori ikeji lẹta naa:
“Ẹyin ọmọ mi ọwọn, mo kọ iwe nnkan wọnyi si yin, ki ẹyin ma ba a dẹṣẹ. Ṣugbọn bi ẹnikẹni ba si dẹṣẹ, awa ni alagbawi lọdọ Baba: Jesu Kirisiti, olododo nikan. Oun si ni etutu si ẹṣẹ wa, ki tilẹ ṣe fun tiwa nikan ṣugbọn fun ẹṣẹ gbogbo araye.” (1Jòhánù 2:1-2)
Ṣe o ri bayẹn? Ọkan lara awọn idi ti Johanu fi kọ lẹta yi si wa ni ki a ma ba a dẹṣẹ. Eyi si fi idi rẹ mulẹ pe ko pọn dandan ki Kirisitiẹni dẹṣẹ. Amọ ṣa o, ti Kiriṣitiẹni ba wa dẹṣẹ, ko nilo lati tẹsiwaju lati ma gbe ninu ẹṣẹ. Idi si ni pe o le ri idariji gba lọwọ Ọlọrun. O le ri idariji gba nitoripe a ni alagbawi kan lọdọ Ọlọrun, iyẹn Jesu Kirisiti. Oun si ni a fa kalẹ gẹgẹ bi etutu fun ẹṣẹ wa ati ẹṣẹ ti gbogbo araye. Idi si niyi ti Ọlọrun ṣe ni lati dariji ẹnikẹni ti o ba jẹwọ ẹṣẹ rẹ. A ti ti ipasẹ Jesu san gbogbo gbese ẹṣẹ araye. Nkan ti ẹnikọọkan kan nilo lati ṣe ni lati tọ Ọlọrun wa fun idariji ẹṣẹ rẹ. O si di dandan ki o ri gba, ti o ba ṣe bẹ ẹ.
Eni ti o ba ti wa ri idariji gba bi eyi gbọdọ bẹrẹ si ni fi tọkantọkan pa ọrọ Ọlọrun mọ. O le ṣe aṣiṣe siwaju tabi sẹyin o. Amọ ko ni tẹsiwaju lati mọ-ọn-mọ ma ṣe aigbọran si ofin Ọlọrun. Tun wo nkan ti Johanu sọ lori eyi:
“Awa mọ pe awa ti wa mọ ọn, bi awa ba n pa ofin rẹ mọ. Ẹni ti o ba wi pe, “Emi mọ ọn,” ti ko si pa ofin rẹ mọ, eke ni, otitọ ko si si ninu rẹ. Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba n pa ofin rẹ mọ, lara rẹ ni a gbe mu ifẹ Ọlọrun pe nitootọ. Nipa eyi ni awa mọ pe awa n wa ninu rẹ. Ẹnikẹni ti o ba wi pe oun n gbe inu rẹ, oun naa pẹlu si yẹ lati maa rin gẹgẹ bi Jesu ti rin.” (1Jòhánù 2:3-6)
Ki ni nkan ti Johanu n fi ẹsẹ wọn mulẹ ninu awọn ẹṣẹ bibeli wọnyi? Ohun naa ni pe a le ma tan ara wa jẹ, ki a si ro wipe a mọ Ọlọrun tabi pe a n ba a rin nitootọ. Gẹgẹ bi o ti ṣe alaye, ẹnikẹni ti o ba sọ wipe oun mọ Ọlọrun yoo ma pa ofin rẹ mọ. Ẹni ti ko ba si ma pa ofin rẹ mọ, sugbọn ti o n sọ wipe oun mọ, nkan n tan ara rẹ jẹ ni. Lafikun, ẹnikẹni ti o ba sọ wipe oun n gbe inu Ọlọrun di dandan ki o ma rin gẹgẹ bi Jesu ti ṣe rin nigba ti O wa laye yi. Ẹnikẹni ti ko ba si ma a ṣe eyi ni ọna ti o han kedere si Ọlọrun ati awọn ti o wa ni ayika rẹ nkan n tan ara rẹ jẹ ni. O wa yẹ ki a bere lọwọ ara wa boya a n ba Ọlọrun rin nitootọ tabi nṣe ni a n tan ara wa jẹ.
Johanu tun tẹsiwaju lori ọrọ yi i kanna lati jẹ ki o ye wa pe biba Ọlọrun rin tabi jijẹ onigbagbọ ninu Kirisiti kọja ọrọ ẹnu lasan. O gbọdọ han ninu irufẹ igbe aye ti a o ma gbe. Irufẹ igbe aye wo si ni o yẹ ki a ma a gbe? Johanu pe ni igbe aye ifẹ. Wo nkan ti o sọ nipa eyi:
“Ẹyin olufẹ ọwọn, ki i ṣe ofin tuntun ni mo n kọwe rẹ si yin ṣugbọn ofin atijọ, eyi ti ẹyin ti gbọ ni atetekọṣe. Ofin atijọ ni ọrọ naa ti ẹyin ti gbọ. Pẹlupẹlu, ofin tuntun ni mo n kọwe rẹ si yin; eyi ti i ṣe otitọ ninu rẹ ati ninu yin, nitori okunkun n kọja lọ, imọlẹ otitọ si n ti n tan. Ẹni ti o ba si wi pe oun n wa ninu imọlẹ, ti o si koriira arakunrin rẹ si n bẹ ninu okunkun. Ẹni ti o ba fẹran arakunrin rẹ, o n gbe inu imọlẹ, ko si si ohun ikọsẹ kan ninu rẹ. Ṣugbọn ẹni ti o ba koriira arakunrin rẹ n gbe ninu okunkun, o si n rin ninu okunkun, ko si mọ ibi ti oun n lọ, nitori ti okunkun ti fọ ọ loju.” (1Jòhánù 2:7-11)
Njẹ o ri bayẹn? Ofin pataki kan ṣoṣo ti Jesu fun awọn ọmọ ẹyin rẹ ni ofin ifẹ, ki wọn ma a rin ninu ifẹ pẹlu ara wọn ati pẹlu gbogbo eniyan. Enikẹni ti o ba wa n rin ninu imọlẹ Ọlọrun di dandan ki o ma rin ninu ifẹ. Idi si ni pe ifẹ ni Ọlọrun, bi Johanu yoo ti ṣe fi ye wa ni ori ikẹrin lẹta yi. Ẹni ti ko ba wa rin ninu ifẹ pẹlu ọmọnikeji rẹ, ti o si n fi ọwọ sọya pe oun mọ Ọlọrun tabi pe o n wa ninu imọlẹ, nkan n tan ara rẹ jẹ ni. Nitorina, ko si nkan ti o n jẹ Kirisitiẹni ni mi ninu ọkan mi, ti ko ba farahan ninu iwa ati iṣesi mi.
Johanu wa tẹsiwaju lati sọ diẹ si lara idi ti o fi kọ lẹta yi ninu awọn ọrọ wọnyi:
“Emi n kọwe si yin, ẹyi ọmọ mi ọwọn, nitori ti a dari ẹṣẹ yin ji yin nitori orukọ rẹ. Emi n kọwe si yin, ẹyin baba, nitori ti ẹyin ti mọ ẹni ti o wa ni atetekọse, Emi n kọwe si yin, ẹyin ọdọmọkurnin, nitori ti ẹyin ti ṣẹgun ẹni ibi naa. Emi n kọwe si yin, ẹyin ọmọde mi ọwọn, nitori ẹyin ti mọ Baba. Emi n kọwe si yin, ẹyin baba, nitori ti ẹyin ti mọ ẹni ti o wa ni atetekọṣe. Emi n kọwe si yin, ẹyin ọdọmọkunrin, nitori ti ẹyin ni agbara, ti ọrọ Ọlọrun si n gbe ninu yin, ti ẹ si ṣẹgun ẹni ibi naa.” (1Jòhánù 2:12-14)
Pẹlu awọn nkan ti o sọ silẹ yi, a ri wipe awọn oye kan wa ti awa ti a jẹ ọmọ Ọlọrun gbọdọ ni. Akọkọ, a ri wipe isọri eniyan mẹta ni Johanu mẹnuba ninu lẹta yi, ti o n fẹ ki oye nkan ti Ọlọrun ti ṣe fun wọn ati ẹni ti wọn jẹ ninu Kirisiti ye. O darukọ awọn baba, awọn ọdọmọkurin ati awọn ọmọde. Ṣe o wa n fi awọn iṣọri ti o mẹnuba yi ṣe apejuwe iṣọri awọn Kirisitiẹni ni, abi bi o ti ṣe ri lọkan rẹ naa ni o ṣe sọ? A le ma le sọ ni pato. Ṣugbọn nkan ti o daju ṣaka ni pe o fẹ ki awọn ti o jẹ Kirisitiẹni ni oye awọn nkan ti o sọ nipa wọnyi, awọn nkan ti o n tọka si ipo ti wọn wa niwaju Ọlọrun.
Ki si ni awọn nkan wọnyi ti o fẹ ki awa ti a jẹ Kirisitiẹni mọ daju ṣaka? Ọkan lara rẹ ni pe a ti dari ẹṣẹ wa ji wa. Ko sọ wipe a o dari ẹṣẹ wa ji wa. Dipo eyi, o sọ wipe a ti dari ẹṣẹ wa ji wa. Lọna wo? Nipa iku ati ajinde Jesu Kiristi! Ki a ma gbagbe pe o ti sọ fun wa tẹlẹ pe Jesu ni Ọlọrun fa kalẹ gẹgẹ bi etutu fun ẹṣẹ wa ati ẹṣẹ gbogbo araye. Nitorina, Ọlọrun ko tun ni lailai ka awọn ẹṣẹ wa si wa lọrun mọ, bi o ti wu ki awọn ẹṣẹ naa buru to. O ti dari gbogbo wọn jin wa. Ti wa ni ki a bẹrẹ si ni rin pẹlu imoye pe a ko ki i ṣe ẹlẹṣẹ mọ ati wipe a le ba Ọlọrun rin bayi lailai bẹru tabi foya.
Nkan keji ti apọsiteli yi fẹ ki a mọ daju ṣaka ni pe a ti ni oye ẹni ti Ọlọrun jẹ nipasẹ Kirisiti Jesu. Nitorina, ti a ba jẹ ki ẹnikẹni tan wa lati sin ọlọrun miran, nṣe ni a n fi han pe a ko i ti fi igba kankan ni ibaṣepọ pẹlu rẹ. Ẹni ti o ba ti wọnu ibaṣepọ pẹlu Ọlọrun nipasẹ Jesu ko tun ni lailai wa ọlọrun miran lọ. Idi si ni pe oye rẹ yoo ti peye pe ko si ọlọrun miran lẹyin Ọlọrun Baba wa, Ẹni ti o da ohun gbogbo.
Nkan ẹkẹta ti Johanu tun fẹ ki a ni oye rẹ ni pe a ti ṣẹgun eṣu, ẹni ibi nii. Ti a ba si tun woye nkan ti o sọ daradara, a o ri wipe ko sọ wipe a o ṣẹgun eṣu. Dipo bẹẹ, o sọ wipe a ti ṣẹgun eṣu. Lọna wo! Nipasẹ igbagbọ wa ninu Kirisiti Jesu ni. Ẹnikẹni ti o ba gbagbọ ninu Jesu, gẹgẹ bi Oluwa ati Olugbala rẹ, ti ṣegun eṣu. Iyẹn jasi pe eṣu ko ni aṣẹ lori aye rẹ mọ. O wa ku sọwọ rẹ lati bẹrẹ si ni gbe aye rẹ gẹgẹ bi ẹni ti eṣu ko ni aṣẹ lori rẹ tabi ki o fi aye silẹ fun eṣu lati ma a ṣe aye rẹ baṣubaṣu, iyẹn bi o ba ti ṣe wu u.
Johanu tun tẹsiwaju lati jẹ ki o ye wa pe a gbọdọ mọ lọkan wa pe alagbara ni a jẹ ninu Kirisiti, a ki i ṣe amúkùn-ún ti eṣu ati awọn ọmọ ogun rẹ kan le ṣe lọsẹ bi o ti ṣe wu wọn. Idi si ni pe Ẹmi Ọlọrun ti n gbe inu wa Ẹmi agbara ni. Awa ni a wa gbọdọ bẹrẹ si ni rin pẹlu imoye pe alagbara ni a jẹ ninu Kirisiti Jesu, ki a si ma fi aye gba eṣu ati awọn ọmọ ogun rẹ lati dẹru ba wa.
Lakotan, Johanu tun n jẹ ki o ye a pe ọrọ Ọlọrun n gbe ninu wa. Ọrọ Ọlọrun wo ni o n gbe inu wa? Jesu ni ọrọ Ọlọrun naa ti o n gbe inu wa. Lọna wo ni o si n gba gbe inu wa? Nipasẹ Ẹmi Mimọ ni! Nitorina, a ko da wa laye yi. Ọlọrun wa pẹlu wa ni gbogbo igba. Idi si ni yi ti a fi ju aṣẹgun lọ. (Wo: 1Jòhánù 3:24)
Niwọn igba ti Johanu ti sọ awọn nkan wọnyi fun wa, a nilo lati fi sọkan pe a yatọ si awọn ti aye yi. Nitorina, iwuwasi wa ati iṣesi wa gbọdọ yatọ patapata si ti wọn. Idi ni yi ti o fi wa bẹrẹ si ni kilọ fun wa, ki a ba le mọ awọn nkan ti a nilo lati yẹra fun, ki a ma ba mu wa ṣina ati ki a ba le pade Jesu pẹlu igboya nigba ti o ba pada de lati wa muwa. Awọn ikilọ wo ni o wa fun wa? Lara rẹ ni iwọnyi:
“Ẹ ma ṣe fẹran aye tabi ohunkohun ti n bẹ ninu aye. Bi ẹnikẹni ba fẹran aye, ifẹ ti Baba ko si ninu rẹ. Nitori ohun gbogbo ti n bẹ ninu aye: ifẹkufẹẹ ti ara, ifẹkufẹẹ ti oju, ati igberaga ti ohun ti o ni ati ohun ti o ṣe ko wa lati ọdọ Baba bi ko ṣe lati ọwọ aye. Aye si n kọja lọ ati ifẹkufẹẹ rẹ, ṣugbọn ẹni ti o ba n ṣe ifẹ Ọlọrun ni yoo wa titi laelae.” (1Jòhánù 2:15-17)
Njẹ o ri bayẹn? A ko le fẹran aye, ki a si tun ro wipe ifẹ Ọlọrun wa ninu wa. Ṣugbọn Ọlọrun funrarẹ fẹran aye. Ṣebi nitori eyi ni o ṣe fun wa ni ọmọ rẹ, Jesu Kirisiti fun irapada wa. Ki wa lo de ti ko fi fẹ ki a fẹran aye? Ko kuku i ṣe wipe Ọlọrun ko fẹ ka fẹran aye tabi ọmọniyan. Nkan ti ko fẹ ni awọn nkan ti awọn ti aye yi fẹ, ti wọn si n yọ tabi ṣogo ninu wọn.
Ki wa ni awọn nkan wọnyi? Awọn naa ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ oju ati igberaga. Ti a ba si wo daradara, awọn nkan wọnyi ni o n ba aye jẹ, awọn nkan wọnyi ni o n ba ibaṣepọ laarin awọn ọmọniyan jẹ. O si wa di dandan ki awọn nkan wọnyi parun pẹlu aye. Ẹni ti o ba wa wa wọn mọya, ti o jẹ ki wọn gba isakoso aye rẹ di dandan ki oun naa parun pẹlu wọn. Kiki awọn ti o ba n ṣe ifẹ Ọlọrun ni yoo ba jọba titi lailai. Ṣe emi wa n ṣe ifẹ Ọlọrun? Ṣe iwọ naa n ṣe ifẹ rẹ?
Ikilọ keji Johanu si wa da lori awọn eke onigbagbọ ti o n ti aarin ijọ jade lọ. O pe wọn ni aṣodi si Kirisiti. O si pe wọn ni aṣodi si Kirisiti lati jẹ ki o ye wa pe ko ki i ṣe ọkunrin egbe ni i, ti awọn wolii Ọlọrun sọ asọtẹlẹ nipa rẹ, nikan a le pe ni aṣodi si Kirisiti. Gbogbo awọn ti ko ba ti gba pe Jesu ni i ṣe Kirisiti ni aṣodi si Kirisiti. Gbogbo wọn patapata ni ọta rẹ. Wọn wa le ti wa ninu ijọ tẹlẹ ri o. Ko ja mọ nkankan. Wọn ko ki i ṣe ti Kirisiti. (Wo: 1Jòhánù 2:18-23)
Bi Johanu ti ṣe sọ, awa ti a jẹ ti Kirisiti ti gba ifororoyan Ẹmi Mimọ lati ọdọ Ọlọrun. Nitorina, a mọ otitọ ninu ọkan wa, otitọ ti n sọni di ominira. O wa ṣe pataki ki a jẹ ki otitọ yi duro digbi sinu wa ti awa naa ba fẹ duro digbi sinu Jesu, ti a ko si fẹ ki ohunkohun ya wa ya a. Niwọn igba ti a ba n ṣe eyi, a ko ni le e ṣi wa lọna. A ko ni le ṣi wa lọna nitoripe Ẹmi Mimọ ti a lo lati yan wa tabi ya wa sọtọ gẹgẹ bi ti Ọlọrun, Ẹmi otitọ ni, ko si ni ṣe alaikọ wa ni awọn nkan ti a nilo lati mọ. Wo nkan ti Johanu sọ lori eyi:
“Nnkan wọnyi ni mo kọwe si yin ni ti awọn ti wọn fẹ ẹ mu yin ṣina. Ṣugbọn ni ti ifororoyan ti ẹyin gba lọwọ rẹ si n gbe inu yin, ẹyin ko tun nilo pe ki ẹnikan kọ yin. Ṣugbọn bi ifoforoyan naa ti n kọ yin ni ohun gbogbo ti o jẹ otitọ, ti ki i si i ṣe eke, ani gẹgẹ bi o si ti kọ yin, ẹ maa gbe inu rẹ.” (1Jòhánù 2:26-27)
Ki ni nkan ti Johanu n sọ ninu awọn ẹsẹ bibeli yi ati ki ni ko sọ? Akọkọ, ko sọ wipe Kirisitiẹni kọọkan ko nilo ki ẹnikẹni kọ ni otitọ ọrọ Ọlọrun mọ nitoripe o ni Ẹmi Ọlọrun ninu rẹ. Ti o ba jẹ wipe nkan ti o n ṣọ niyi, a jẹ wipe oun gan ko lẹtọ lati kọ lẹta si wa lati kọ wa ni ohunkohun. Ṣugbọn nkan ti o n sọ kọ ni pe a ko le kọ wa ni ohunkohun mọ, niwọn igba ti a ti ni Ẹmi mimọ ninu wa. Nkan ti o n sọ ni pe Ẹmi Ọlọrun ti o ngbe ninu gbogbo wa ti to lati kọ gbogbo wa ni ohun gbogbo ti o n jẹ otitọ ti a ni lati mọ. Lọna wo? Nipasẹ awọn olukọ ti o ti yan si aarin wa! Awọn olukọ wọnyi ko si ni kọ wa ni ohunkohun ti o yatọ si nkan ti o wa ninu Iwe mimọ. Nitorina, ti a ba joko ti nkan ti wọn n kọ wa, o ti to lati ṣe wa yẹ ninu ifẹ Ọlọrun ati lati ri daju pe a ko ṣi wa lọna.
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Niparipari, Johanu gba wa ni yanju lẹẹkan si lati ri daju pe a n gbe inu Kirisiti nipa fifi aye gba ọrọ rẹ lati ma gbe inu wa. Nipa bayi, a o le ni igboya lati pade rẹ nigba ti o ba de. Ranti wipe, a sọ fun wa ninu iwe mimọ wipe awọn kan yoo gbiyanju lati fi ara wọn pamọ fun Jesu nigba ti O ba pada de ninu ogo nla rẹ Ti awa naa ko ba fẹ ki eyi ṣẹlẹ si wa, a gbọdọ mu awọn nkan ti Johanu kọ silẹ fun wa ninu lẹta yi ni pataki. Njẹ ki Ẹmi Ọlọrun ran wa lọwọ lati ma fi igba gbogbo ṣe bẹẹ gẹgẹ. Amin. (Wo: 1Jòhánù 2:28-29; Ìfihàn 6:15-17)
ÌBÉÈRÈ
– Bawo ni a ṣe le mọ pe a n tan ara wa jẹ gẹgẹ bi Kirisitiẹni?
– Njẹ o ṣeeṣe nitootọ lati pade Jesu pẹlu igboya nigba ti O ba de?
Láti ọ́wọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2025 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)
ÀKỌ́RÍ: 1JÒHÁNÙ 1-ÌMỌ́LẸ̀ NI ỌLỌ́RUN | ÀYỌKÀ: 1JÒHÁNÙ 1:1-10 | ỌJỌ́RÚ 25, ÒKÚDÙ 2025
ÀKỌ́SÓRÍ: “Eyi si ni iṣẹ ti awa ti gbọ lẹnu rẹ ti awa si n jẹ fun yin: pe imọlẹ ni Ọlọrun; ni ọdọ rẹ ko si okunkun rara.” (1Jòhánù 1:5)
Ọ̀RỌ̀ ÌSÀÁJÚ
Lẹta akọkọ Johanu jẹ ọkan lara awọn lẹta ti o kọ si awọn ọmọ Ọlọrun lati ran wọn lọwọ ninu igbagbọ wọn. O si kọ lẹta yi lati jẹ ki a mọ wipe nipa igbagbọ wa ninu Kirisiti Jesu, a ti fun wa ni iye ainipẹkun ati wipe a ti pe wa sinu ibadapọ pẹlu Ọlọrun imọlẹ ati Jesu Kirisiti ọmọ rẹ. O si n sọ eyi fun wa ki a ba a le mọ pataki ki a ma ṣe amulo iye ainipẹkun ti a fun wa ninu Kirisiti lati rin pẹlu Ọlọrun ninu imọlẹ ati lati yẹra fun itanraẹnijẹ. Asiko ti ọ kọ lẹta yi ati igba ti o kọ ni a le ma le mọ daju. Ṣugbọn a ri ninu lẹta naa wipe ni asiko ti o kọ, ọpọlọpọ eke Kirisitiẹni ni o ti n jade lọ lati inu ijọ. Nitorina, o ṣeeṣe ki o jẹ wipe iyinrere Kirisiti ti tan de ọpọlọpọ ibi ni asiko ti o kọ lẹta naa. Eyi ti o wa wu ki o jẹ, nkan ti o ṣe pataki ju fun wa ni lati mọ nkan ti o kọ sinu lẹta naa ati bi o ti ṣe le ran igbagbọ wa lọwọ ni asiko ti a wa yi. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun ṣi ọkan wa paya lati ri ohun gbogbo ti O fẹ ki a ri ninu lẹta naa ati lati ṣe amulo wọn ni ọna ti o peye. Amin.
ÌMỌ́LẸ̀ NI ỌLỌ́RUN
Wayi o, ni ori kinni lẹta yi, Johanu jẹ ki a mọ wipe Ọlọrun ti jẹ ki iye ainipẹkun rẹ farahan nipasẹ ọmọ rẹ Jesu Kirisiti. O si ṣe eyi ki a ba a le wa ni ibadapọ pẹlu rẹ, lẹyin igba ti ẹṣẹ ti fi iyapa si aarin wa, ti o si ti jẹ ki a kuna ogo rẹ. Iwọ naa wo nkan ti o sọ lori eyi:
“Eyi ti o wa lati atetekọṣe, ti awa ti gbọ, ti awa ti fi oju wa ri, ti awa si ti tẹjumọ, ti ọwọ wa si ti di mu, eyi ti a kede; ni ti ọrọ iye; Iye naa si ti farahan, awa si ti ri i, awa si n jẹri, awa si n sọ ti iye ainipẹkun naa fun yin, ti o ti n bẹ lọdọ Baba, ti o si farahan fun wa. Awa n sọ fun yin, eyi ti awa ti ti ri, ti awa si ti gbọ, ki ẹyin pẹlu ki o le ni idapọ pẹlu wa. Nitootọ idapọ wa si n bẹ pẹlu Baba ati pẹlu ọmọ rẹ, Jesu Kirisiti. Awa si kọwe nnkan wọnyi si yin, ki ayọ yin ki o le di kikun.” (1Jòhánù 1:1-4)
Ki ni Johanu n sọ nibiyi? Ohun naa ni pe oun ati awọn ọmọlẹyin igbaani ni anfaani ti ko wọpọ lati ri iye ti Ọlọrun ran wa sinu aye ati lati ni ibaṣepọ ti o peye pẹlu rẹ. Njẹ eyi wa jasi pe awa ti ko ni irufẹ anfaani yi ko le mo iye ainipẹkun yi, ki a si tun ni ibaṣepọ ti o peye pẹlu rẹ? Rara o! Awa naa le e mọ, ki a si tun ni ibaṣepọ ti o peye pẹlu rẹ. Lọna wo? Nipasẹ Ẹmi Ọlọrun! (Wo: Jòhánù 16:7)
Ni kukuru, nkan ti Johanu fẹ ki a mọ ninu awọn ẹsẹ bibeli wọnyi ni pe nipasẹ igbagbọ wa ninu Jesu Kirisiti, a ti mu wa wa sinu ibadapọ pẹlu rẹ ati Ọlọrun Baba. Eyi yasi pe a ko nilo lati danikan gbe ile aye mọ. Bẹẹni, a ko nilo lati gbe ile aye bi igba ti a ko ni alabaro tabi oluranlọwọ. Ọlọrun Baba wa, Jesu Kirisiti Oluwa wa ati Ẹmi Mimọ wa pẹlu wa lati ba wa gbe ile aye ati lati ṣe wa ni aṣẹgun ni gbogbo ọna ati lori ohun gbogbo.
O wa ṣeni laanu pe ọpọ awa ti a pe ara wa ni Kirisitiẹni ni a n da gbe ile aye. Ọpọ wa ni o n da ija wọn ja laye yi. Idi si ni yi ti a fi n fi idi rẹmi ni ọpọ ọna, ti eṣu ati awọn ọmọ ogun rẹ si n bori wa. Amọ ni kete ti a ba bẹrẹ si ni rin pẹlu imọra ati oye pe Ọlọrun, Jesu Kirisiti ati Ẹmi mimọ wa pẹlu wa ninu irin ajo wa ni aye yi, ko si irufẹ idojukọ naa ninu aye yi ti yoo bori wa.
Ọna kan pataki lati wa rin pẹlu imọra ati oye pe a n ba Ọlọrun rin ni ki a ma rin ninu imọlẹ. Ki ni idi ti a ṣe nilo lati ma a rin ninu imọlẹ? Idi akọkọ, gẹgẹ bi Johanu ti ṣe fi ye wa ninu ori ikinni lẹta yi, ni pe imọlẹ ni Ọlọrun. Niwọn igba ti Ọlọrun si jẹ imọlẹ, ẹnikẹni ti o ba n rin ninu okunkun ko le sọ wipe oun n ba Ọlọrun rin. Eyi jasi pe ẹni ti o ba n ṣe nkan ikọkọ, awọn nkan itiju ati iwọsi, ko le sọ wipe oun n ba Ọlọrun rin. Ẹni ti o ba n ba Ọlọrun rin nitootọ yoo duro sinu imọlẹ, yoo duro si ibi ti awọn iṣẹ rẹ yoo ti han gbangba-gbangba si awọn eniyan pe iṣẹ ire ni wọn.
Ṣe eyi wa tunmọ si pe ẹni ti o ba n rin pẹlu Ọlọrun imọlẹ ko le ṣe aṣiṣe rara? O ti o! O le ṣe aṣiṣe. Ṣugbọn niwọn igba ti o jẹ wipe inu imọlẹ ni o wa, bi o tilẹ ṣe aṣiṣe, ni kiakia ni yoo ri wipe oun ti ṣe aṣiṣe ati wipe oun nilo lati ronupiwada, ki o n si ṣe atunṣe. Iwọ naa wo nkan ti Johanu sọ lori eyi:
“Eyi si ni iṣẹ ti awa ti gbọ lẹnu rẹ ti awa si n jẹ fun yin: pe imọlẹ ni Ọlọrun, ni ọdọ rẹ ko si okunkun rara. Bi awa ba wi pe awa ni idapọ pẹlu rẹ, ti awa si n rin ninu okunkun, awa n ṣeke, awa ko si gbe ninu otitọ. Ṣugbọn bi awa ba n rin ninu imọlẹ, gẹgẹ bi oun ti n wa ninu imọlẹ, awa ni idapọ pẹlu ara wa, ati pe ẹjẹ Jesu Kirisiti, Ọmọ rẹ, wẹ wa nu kuro ninu ẹṣẹ gbogbo.” (1Jòhánù 1:5-7)
Njẹ o ri bayẹn? Imọlẹ ni Ọlọrun, ko si si ohunkohun ti o ni i ṣe pẹlu okunkun ninu rẹ tabi lọdọ rẹ. Eyi n jẹ ki o ye wa pe ẹni ti yoo ba ba Ọlọrun rin gbọdọ ṣetan lati jẹ ki imọlẹ tan si aye rẹ, ki o ba le e ri ara rẹ bi o ti ri, ki o si ba a le mojuto awọn nkan ti o ni i ṣe pẹlu eeri tabi iwa-aida ti o ba wa ninu rẹ. Ẹnikẹni ti o ba wa sọ wipe oun ni idapọ pẹlu Ọlọrun, ti o si tun wa n rin ninu okunkun n tan ara rẹ jẹ ni – ko si otitọ ninu iru ẹni bẹ. Kiki awọn ti o ba n rin ninu imọlẹ ifẹ Ọlọrun nikan ni o wa ni idapọ pẹlu rẹ, ti ẹjẹ Kirisiti yoo si maa fi igba gbogbo fọ mọ kuro ninu ẹṣẹ wọn gbogbo.
Siwaju si, Johanu tun jẹ ki o ye wa pe ẹni ti o ba n rin ninu imọlẹ Ọlọrun nitootọ ko ni dọwọbo ẹṣẹ rẹ mọlẹ. Irufẹ ẹni bẹ ko ni ma ba Ọlọrun jiyan lori ẹṣẹ rẹ tabi lori ohun yowu ti o n ṣe ti ko tọ. Nikete ti a ba ti fi han pe o da ẹṣẹ tabi pe o ṣe nkan ti ko tọ ni yoo gba wipe oun ṣẹ, ti yoo si tọrọ aforiji lọwọ Ọlọrun. Wo nkan ti Johanu sọ lori eyi:
“Bi awa ba wi pe awa ko ni ẹṣẹ, awa n tan ara wa jẹ, otitọ ko si si ninu wa. Bi awa ba jẹwọ ẹṣẹ wa, oloootọ ati olododo ni oun lati dari ẹṣẹ wa ji wa, ati lati wẹ wa nu kuro ninu aiṣododo gbogbo. Bi awa ba wi pe awa ko dẹṣẹ, awa mu un ni eke, ọrọ rẹ ko si si ninu wa.” (1Jòhánù 1:8-10)
Njẹ o ri bayẹn? Ọna akọkọ lati mọ daju pe a n ba Ọlọrun rin nitootọ ni pe a ko ni sa fun imọlẹ rẹ tabi imọlẹ ọrọ rẹ. A ko ni ma fi ara pamọ ṣe awọn nkan ti ko yẹ. Ọna ekeji ni wipe a ko ni ma a ba Ọlọrun jiyan lori awọn nkan ti O n tan imọlẹ si ninu aye wa ti ko dara. Awọn ti ko ba si ba a jiyan ni yoo dari ẹṣẹ wọn jin wọn, ti yoo si tun fọ aiṣododo wọn gbogbo danu.
Ki si ni idi? Idi ni pe Jesu ti ku fun ẹṣẹ gbogbo araye, bi a o ti ṣe ri ninu ori keji lẹta Johanu yi (1Jòhánù 2:2). Nitorina, ẹnikẹni ti o ba ti jẹwọ ẹṣẹ rẹ di dandan ki o ri idariji ati iwẹnumọ gba lọwọ Ọlọrun. Idi niyi ti Johanu ṣe sọ wipe olootọ ati olododo ni Ọlọrun lati dari ẹṣẹ wa ji wa ati lati wẹ wa nu kuro ninu aiṣododo wa gbogbo. O tunmọ si pe Ọlọrun ko le ṣe alaima dari ẹṣẹ ji ẹnikẹni ti o ba yẹwọ rẹ.
Amọ ẹni ti o ba kọ lati jẹwọ ẹṣẹ rẹ, ti o kọ lati gba wipe otitọ ni nkan ti Ọlọrun sọ lori ẹṣẹ oun n mu Ọlọrun ni opurọ ati eke. Eyi si wa tunmọ pe ọrọ Ọlọrun ko si ninu irufẹ ẹni bẹ. Ti a ba si wo daradara, ẹni naa le ma ti di ọmọ Ọlọrun rara.
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Nkan pataki ti Johanu fẹ ki a mọ ninu ori kinni lẹta rẹ ni pe imọlẹ ni Ọlọrun. Nitorina, ẹnikẹni ti o ba ni idapọ pẹlu rẹ nitootọ ko ni duro sinu okunkun tabi kọ lati gbe igbesẹ ti o wa ni ibamu pẹlu awọn nkan ti imọlẹ Ọlọrun ti o n tan sinu aye rẹ ba fi han an. Ki a wa bi ara wa lere boya a wa ninu ibadapọ pẹlu Ọlọrun nitootọ tabi nṣe ni a n tan ara wa jẹ. Iha ti a ba kọ si imọlẹ rẹ ni yoo sọ boya lotitọ ni a wa ninu ibadapọ pẹlu rẹ tabi a ko si ninu ibadapọ pẹlu rẹ.
ÌBÉÈRÈ
– Ki ni ẹnikẹni ti o ba fẹ ba Ọlọrun rin gbọdọ fi sọkan gẹgẹ bi Johanu ti ṣe fi han ninu ori kinni lẹta akọkọ rẹ?
– Ki ni o ro wipe o le fa ti Kirisitiẹni kan fi le mu Ọlọrun ni opurọ lori ohun ti o tọ ati eyi ti ko tọ?
Láti ọwọ́ Johnson O. Lawal
Copyright © 2025 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)
ÀKỌ́RÍ: 2PÉTÉRÙ 3-ỌJỌ́ OLÚWA | ÀYỌKÀ: 2PÉTÉRÙ 3:1-18 | ỌJỌ́RÚ 04, ÒKÚDÙ 2025
ÀKỌ́SÓRÍ: “Ṣugbọn, olufẹ, ẹ ma ṣe gbagbe ohun kan yii, pe ọjọ kan lọdọ Oluwa bi ẹgbẹrun ọdun ni o ri, ati ẹgbẹrun ọdun bi ọjọ kan.” (2Pétérù 3:8)
Ọ̀RỌ̀ ÌSÀÁJÚ
Bi a ti ṣe ri ninu awọn ẹkọ ti a kọ sẹyin ninu lẹta keji Peteru si awọn ọmọ Ọlọrun, pataki idi ti o ṣe kọ lẹta yi ni lati ru wa soke lati ma fi igba gbogbo wa ni imurasilẹ de bibọ Jesu. Ni ṣiṣe eyi, o ki wa nilọ nipa awọn eke oniwaasu ti wọn yoo wa ni aarin wa ni awọn ọjọ ikẹyin wọnyi lati ṣi wa lọna ati lati fi idibajẹ sinu igbagbọ wa. Yoo si dara pupọ ti a ba le kọbiara si awọn nkan ti o sọ wọnyi, ki a ba a le wa ni iduro ṣinṣin nigba ti Jesu Kirisiti Oluwa wa ba de.
ỌJỌ́ OLÚWA
Amọ ṣa o, awọn oniwaasu eke nikan kọ ni Peteru fẹ ki a ṣọra ati yẹra fun o; o tun fẹ ki a ṣọra, ki a si tun yẹra fun awọn ẹlẹgan ti yoo dide ni aarin wa. Ki si ni idi? Idi ni wipe awọn wọnyi naa le bu omi tutu si ọkan wa, ki wọn si jẹ ki a ma mu igbagbọ ati ireti wa ninu ipadabọ Jesu ni pataki mọ. Eyi si ni ewu gidigidi fun ọkan wa. Nitorina, Peteru ki wa nilọ, o si tun gba wa niyanju, ni ori kẹta lẹta rẹ ti a n gbe yẹwo ninu ẹkọ yi lati fun wa ni idaniloju lori ọjọ Oluwa, awọn nkan ti o sorọ mọ ati iha ti o yẹ ki a kọ si i. Iwọ naa kọkọ wo diẹ lara awọn nkan ti o sọ:
“Olufẹ, eyi ni iwe keji ti mo n kọ si yin, ninu mejeeji naa ni emi n ru ero inu yin soke nipa riran yin leti; Ki ẹyin le maa ranti ọrọ ti a ti ẹnu awọn wolii mimọ sọ ṣaaju, ati ofin Oluwa ati Olugbala wa lati ọdọ awọn apọsiteli yin. Ki ẹ kọ mọ eyi pe, nigba ọjọ ikẹyin, awọn ẹlẹgan yoo de pẹlu ẹgan wọn. Wọn o maa rin nipa ifẹ ara wọn. Wọn o si maa wi pe, “Nibo ni ileri wiwa rẹ gbe wa? Lati igba ti awọn baba ti sun, ohun gbogbo n lọ bi wọn ti wa ri lati igba ọjọ yii wa.” Nitori eyi ni wọn mọọmọ ṣe aifẹ mọ pe nipa ọrọ Ọlọrun ni awọn ọrun ti wa lati igba atijọ ati ti ilẹ yọri jade ninu omi, ti o si duro ninu omi. Nipa eyi ti omi bo aye ti o wa nigba naa ti o si ṣegbe. Ṣugbọn awọn ọrun ati aye, ti o n bẹ nisinsinyii, nipa ọrọ kan naa ni o ti to jọ bi iṣura fun ina, a pa wọn mọ de ọjọ idajọ ati iparun awọn alaiwa-bi-Ọlọrun. Ṣugbọn, olufẹ, ẹ ma ṣe gbagbe ohun kan yii, pe ọjọ kan lọdọ Oluwa bi ẹgbẹrun ọdun ni o ri, ati ẹgbẹrun ọdun kan bi ọjọ kan. Oluwa ko fi ileri rẹ jafara, bi awọn elomiran ti ka ijafara si; ṣugbọn o n mu suuru fun yin nitori ko fẹ ki ẹnikẹni ṣegbe, bi ko ṣe ki gbogbo eniyan wa si ironupiwada.” (2Pétérù 3:1-9)
Njẹ o ri bayẹn? Peteru funrarẹ jẹ ki o ye wa nibiyi pe lẹta keji ti oun yoo kọ si ijọ eniyan Ọlọrun ni eyi. O si kọ awọn lẹta yi lati ru wa soke ni ṣiṣe ifẹ Ọlọrun nipa mimu awọn akọsile Iwe mimọ ni pataki. O wa tẹsiwaju, bi mo ti ṣe pe akiyesi wa si tẹlẹ, lati jẹ ki o ye wa pe ara awọn arisi awọn ọjọ ikẹyin ni pe awọn ẹlẹgan yoo dide ninu ijọ Ọlọrun. Ki ni idi ti o ṣe pe wọn ni ẹlẹgan? Idi ni pe awọn wọnyi yoo maa rin ninu ifẹkufẹ ara wọn. Ki si ni idi ti wọn yoo fi maa rin ninu ifẹkufẹ ara wọn? Idi ni wipe wọn ko gbagbọ ninu ipadabọ Kiristi Jesu Oluwa wa.
Bi Peteru ṣe tẹsiwaju lati jẹ ki o ye wa, awọn ẹlẹgan wọnyi yoo ma jẹ ki o ye wa pe ẹtan lasan ni ileri bibọ Jesu ati wipe ko i ti si nkan ti o yipada laye yi lati igba ti a ti n waasu nipa bibọ rẹ. Nkan ti wọn yoo si maa gbiyanju lati sọ ni pe, “Ti o ba jẹ pe Jesu n bọ nitootọ, o yẹ ki O ti de.”
Ti a ba si fojusunukun wo nitootọ, o ti pẹ ti a ti n waasu nipa bibọ Jesu. Ki wa lo de ti ko i ti de? Ẹnikẹni ti ko ba fiyesi ọrọ Iwe Mimọ daradara, ki o si mu ni ọkunkundun, le titori eyi gbe ireti rẹ ju sọnu, ki o si bẹrẹ si ni ṣi iwa wu. Ti Jesu ba a wa lọ de ba irufẹ ẹni bẹ ẹ ni ipo yi, a jẹ wipe igbagbọ rẹ ti pada ja si ofo niyẹn.
Idi si niyi ti Peteru fi n kilọ fun wa pe ki a ma jẹ ki ẹlẹgan ọrọ Ọlọrun kankan ṣi wa lọna o. Idi ni wipe awọn ẹlẹgan wọnyi n mọọmọ gbe ọrọ Ọlọrun sẹgbẹ kan ni. Bawo ni a ṣe ṣẹda aye ati ọrun? Nipasẹ ọrọ Ọlọrun ni! Bawo ni ikun omi ṣe wa sori aye nigba Nóà? Nipasẹ ọrọ Ọlọrun ni! Nipasẹ ọrọ yi kan naa si ni a o fi opin si aye ati awọn ọrun ti o wa nisinsinyi. Lọna wo? Nipa dida ina sun wọn! Peteru tilẹ jẹ ki o ye wa pe nṣe ni a pa awọn ọrun ati aye yi mọ fun iparun.
Ki wa lo fa ti opin ati iparun ko i ti de ba aye ati awọn ọrun asiko yi? Ki ni o fa ti ọjọ Oluwa ko i ti de, ki Jesu si padawa lati ko awọn ayanfẹ rẹ ati lati fi opin si ohun gbogbo ti o n lọ ninu awọn ọrun ati aye igba yi? Idi akọkọ, gẹgẹ bi Peteru ti fi ye wa, ni pe ọna ti awọn n gba ka ọjọ, igba ati asiko kọ ni Ọlọrun n gba ka wọn. Fun awa, ọjọ, igba tabi asiko le lọ. Ṣugbọn fun Ọlọrun, ọjọ, igba ati asiko ko le lọ si ibi kankan. Idi si ni pe ninu ayeraye ni Ọlọrun n gbe. Nitorina, oju ko le e kan. Bi Peteru tilẹ ti sọ fun wa, ko si iyatọ laarin ọjọ kan ati ẹgbẹrun ọdun niwaju Ọlọrun. Bakanna ni wọn ṣe ri.
Nitori eyi, ti ba n wo wipe o yẹ ki Jesu ti de, nitoripe a woye wipe ọpọlọpọ ọdun ni o ti kọja lẹyin igba ti a ti gba a sinu awọn ọrun, Ọlọrun ko ri eyi ro rara. Idi si ni pe O ti yan ọjọ ti yoo fi opin si ohun gbogbo, ti yoo si ṣe idajọ awọn eniyan. Amọ ko si ẹni ti o mọ ọjọ yi. Ti ọjọ yi ko ba si wa pe, ko si bi o ti ṣe dabi ẹni pe o pẹ to ni oju wa, opin ohun gbogbo ko le waye. (Wo: Mátíù 24:42; Ìṣe Àpọ́sítélì 17:31)
Idi keji ti Jesu Oluwa wa ko i ti pada de, ki opin ohun gbogbo si bẹrẹ si ni waye, ni pe Ọlọrun n mu suuru fun gbogbo awọn eniyan. Ki ni idi? Idi ni pe ko fẹ ki ẹnikẹni ṣegbe. Njẹ eyi wa jasi pe gbogbo awọn eniyan ni yoo di ẹni igbala bi? Rara o! Kiki awọn ti o ba gba ọrọ Ọlọrun fun igbala wọn gbọ ni ko ni ṣegbe? Ni asiko Nóà, ọrọ rẹ fun igbala ni ki awọn eniyan wọ inu ọkọ ti o gbe kalẹ. Ni asiko Lọọti, ọrọ rẹ fun igbala ni ki Lọọti ati eni yowu ti o ba gbọ tirẹ sa asala kuro ninu Sodomu ati Gomora ki idajọ to wa sori wọn. Ni oni, ọrọ rẹ si igbala ni ki a gba Jesu Kirisiti gbọ gẹgẹ bi Oluwa ati Olugbala wa, ki a ba a le gba wa lọwọ ẹṣẹ wa, ki a si di ẹni irapada. Ẹnikẹni ti ko ba wa gba ọrọ yi gbọ di dandan ki o ṣegbe nigba ti ọjọ Oluwa ba de.
Amọ ṣa o, ọpọ ni yoo ṣegbe ṣaaju ọjọ Oluwa. Idi si ni pe iku yoo ba wọn ninu ẹṣẹ ati aigbagbọ wọn. Nitorina, bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun n mu suuru fun awọn eniyan lati ronupiwada, ki wọn si gba ọrọ rẹ fun igbala wọn gbọ, ẹnikẹni ti o ba kọ lati ronupidawa ni asiko di dandan ki o ṣegbe sinu iku tabi ni igba ti ọjọ Oluwa ba de.
Igba wo wa ni ọjọ Oluwa yoo de? Bi mo ti ṣe sọ siwaju, ko si ẹni ti o mọ ọn. Ti wa kan ni ki a mura silẹ de e, ki ọjọ naa ma ba a ba wa ni ojiji, ki a si padanu ọkan wa sinu ọrun egbe. Wo nkan ti Peteru sọ fun wa lori eyi?
“Ṣugbọn ọjọ Oluwa n bọwa bi ole ni oru; ninu eyi ti awọn ọrun yoo kọja lọ pẹlu ariwo nla, ati awọn imọlẹ oju ọrun yoo si ti inu ooru gbigbona gidigidi di yiyọ, aye ati awọn iṣẹ ti o wa ninu rẹ yoo si jona luuluu. Njẹ bi gbogbo nnkan wọnyi yoo ti yọ bẹẹ, iru eniyan wo ni ẹyin iba jẹ ninu iwa-mimọ gbogbo ati iwa-bi-Ọlọrun. Ki ẹ maa reti ki ẹ si maa mura giri de dide ọjọ Ọlọrun, nitori eyi ti awọn ọrun yoo gbina, ti wọn yoo di yiyọ, ti awọn imọlẹ rẹ yoo si ti inu ooru gbigbona gidigidi di yiyọ. Ṣugbọn gẹgẹ bi ileri rẹ, awa n reti awọn ọrun tuntun ati aye titun ninu eyi ti ododo n gbe. Nitori naa, olufẹ, bi ẹyin ti n reti iru nnkan wọnyi, ẹ mura giri, ki a le ba yin ni alaafia ni ailabawọn, ati ni ailabuku loju rẹ. Ki ẹ si maa ka a si pe suuru Oluwa wa igbala ni; bi Pọọlu pẹlu arakunrin wa olufẹ, ti kọwe si yin gẹgẹ bi ọgbọn ti a fi fun un. Bi o ti n sọrọ nnkan wọnyi pẹlu ninu iwe rẹ gbogbo ninu eyi ti ohun miiran ṣoro lati ye ni gbe wa, eyi ti awọn ope ati awọn alaiduro nibikan n lọ, bi wọn ti n lọ iwe-mimọ iyoku, si iparun ara wọn. Nitori naa ẹyin olufẹ, bi ẹyin ti mọ nnkan wọnyi tẹlẹ, ẹ maa kiyesara, ki a ma baa fi iṣina awọn eniyan buburu fa yin lọ, ki ẹ si ṣubu kuro ni iduro-ṣinṣin yin. Ṣugbọn ẹ maa dagba ninu oore-ọfẹ ati ninu imọ Oluwa ati Olugbala wa Jesu Kirisiti; ẹni ti ogo wa fun nisinsin yii ati titi lae. Amin.” (2Peteru 3:10-18)
Ki ni a ri nibiyi? Akọkọ, a ri wipe o didan ki ọjọ Oluwa Oluwa de. Ekeji, a ri wipe ọjọ Oluwa yoo de bi ole ni oru ni. Eyi jasi pe ko si ẹni ti o mọ ọjọ naa. Ẹkẹta, a ri wipe ọjọ Oluwa yoo mu iparun ati opin ba awọn ọrun ati aye yi ati ohun gbogbo ti o n lọ ninu wọn. Nitorina, aye yi ko ki i ṣe eyi ti ẹnikẹni le fi ṣe ere jẹ. Idi si niyi ti a ko fi gbọdọ jẹ ki ohunkohun ninu aye naa jẹ ki a padanu ọkan wa. (Wo: Mátíù 16:26)
Amọ ṣa o, ọjọ Oluwa yi ko ni lati de ba awọn ti o gbagbọ ninu Kirisiti Jesu bi ole ni oru. Idi si ni pe a ti sọ fun wa saaju pe o di dandan ki ọjọ naa de. Nitorina, nṣe ni o yẹ ki a wa ni imurasilẹ de e. Eyi si wa lara awọn nkan ti Peteru tẹnumọ fun wa ninu abala lẹta rẹ ti n gbe yẹwo yi. O sọ wipe niwọn igba ti a ti mọ pe o di dandan ki ọjọ Oluwa de ba wa lorilẹ aye yi, nṣe ni o yẹ ki a fi ara wa jin fun iwa mimọ ati iwa-bi-Ọlọrun, ki ba a le wa ni alaafia pẹlu rẹ ati ni ailabuku tabi abawọn niwaju rẹ nigba ti ọjọ yi ba de, ti a o si fi idi ọrun tuntun ati aye tuntun lọlẹ, ni ibamu pẹlu ileri rẹ.
Yatọ si eyi, Peteru tun pe akiyesi wa si ọrọ Apọsiteli Pọọlu pẹlu. O jẹ ki o ye wa pe oun nikan kọ ni oun kilọ fun awọn ọmọ Ọlọrun lori awọn nkan wọnyi. Pọọlu naa n ṣe nkan kanna ninu awọn iwaasu ati lẹta rẹ, bi o tilẹ jẹ wipe awọn eniyan a ma lọ ọrọ rẹ lọrun. Eyi si n jẹ ki o ye wa pe ko si iyapa laarin awọn apọsiteli igbaani wọnyi – ọkan ni gbogbo wọn ri ara wọn si.
Nitorina, ti a ba ri awọn ti wọn n sọ wipe ko yẹ ki a ka awọn lẹta Pọọlu kun rara, a si ri wọn loni ninu ijọ, nṣe ni ki a mọ wipe ara awọn alailoye ti awọn apọsiteli igbaani n kilọ fun wa pe ki a yẹra fun niyẹn. A si gbọdọ yẹra fun wọn, ki wọn ma ba ṣi wa lọna. Peteru, pẹlupẹlu, si sọ eyi bi o ti ṣe n pari lẹta yi. O ni ki a kiyesara, ki a ma ba tipasẹ iṣina awọn eniyan buburu tan wa kuro ninu otitọ, ki a si gbe wa ṣubu.
Ni afikun, ni opin lẹta rẹ, Peteru jẹ ki o ye wa pe a nilo lati fi ara wa jin fun awọn nkan ti yoo jẹ ki a dagbasoke ninu oore-ọfẹ ati imọ Kirisiti Jesu Oluwa ati Olugbala wa. Eyi n jẹ ki o ye wa pe ti a o ba wa ni imurasilẹ de ọjọ Oluwa, a nilo lati ma fi ojoojumọ dagba soke ninu ẹmi. A ko gbọdọ joko tẹtẹrẹ. Aijẹbẹ, bi ole loru ni ọjọ Oluwa yoo ṣe de ba wa.
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
O di dandan ki ọjọ Oluwa de. Suuru Ọlọrun ni ko si ti jẹ ki o de. Nitorina, a ko gbọdọ kọbiara si ọrọ awọn ẹlẹgan ti o n sọ wipe imurasilẹ wa de bibọ Jesu ko ni itumọ. O ni itumọ. Eyi yoo si han gbangba-gbangba si gbogbo eniyan nigba ti ọjọ naa ba de. Nitori eyi, nṣe ni ki a ma a fi ojoojumọ mura silẹ de ọjọ yi nipa fifi ara wa jin fun igbe aye iwa mimọ ati ododo.
ÌBÉÈRÈ
– Ki ni aridaju pe Jesu yoo pada wa nitootọ?
– Njẹ o ri ohun tuntun kankan di mu ninu ẹkọ yi? Ki ni nkan naa?
Láti ọwọ́ Johnson O. Lawal
Copyright © 2025 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)
ÀKỌ́RÍ: 2PÉTÉRÙ 2-OLÙKỌ́NI ÈKÉ | ÀYỌKÀ: 2PÉTÉRÙ 2:1-22 | ỌJỌ́RÚ 14, ÈBÌBÍ 2025
ÀKỌ́SÓRÍ: “Owe otitọ naa ṣẹ si wọn lara, “Aja tun pada si eebi ara rẹ; ati ẹlẹdẹ ti a ti wẹmọ tun pada n yiraa ninu ẹrọfọ.”” (2Pétérù 2:22)
Ọ̀RỌ̀ ÌSÀÁJÚ
Ni ori ikinni lẹta Peteru keji si awọn ọmọ Ọlọrun ti a n gbe yẹwo ninu awọn ẹkọ yi, o ba wa sọrọ lori pataki ki a ma a ṣe aisinmi lati ṣe amulo awọn ipese Ọlọrun fun wa lati gbe igbe aye ti o tẹ ẹ lọrun ati lati ri wipe ipe ati yiyan wa daju. O tun ba wa sọrọ lori imurasilẹ rẹ lati pari ere ije rẹ laye ati ohun ti o fẹ fi asiko ti o ku fun un ṣe. O si tun wa jẹ ki o ye wa pe igbagbọ wa ninu Kirisiti Jesu ko da lori itan asan tabi itan arosọ rara; dipo bẹẹ, o da lori awọn iṣẹlẹ ti o ṣẹlẹ, ti wọn si ni awọn ẹlẹri ti o koju osuwọn. Nitorina, a nilo lati mu igbagbọ wa ni ọkunkundun, ki a si ma jẹ ki ohunkohun jẹ ki a kọ ọ silẹ. Aijẹbẹ, a ko ni wa ni imurasilẹ de bibọ Jesu.
OLÙKỌ́NI ÈKÉ
Lara awọn nkan ti o wa lẹ jẹ ki a gbe igbagbọ wa ninu Kirisiti Jesu ju sọnu tabi ki a jẹ ki idibajẹ ba a ni awọn ti Peteru pe ni olukọni eke. Ti a ko ba gbagbe, ni ori kinni lẹta yi, apọsiteli yi jẹ ki o ye wa pe a nilo lati gbe ọrọ Ọlọrun ti a ri ninu Iwe mimọ leke ohun gbogbo, leke gbogbo iran, isọtẹlẹ, ifedefọ, iṣẹ-iyanu, ifarahan awọn angẹli ati bẹẹbẹẹ lọ. Idi si ni wipe awọn wolii ti a lo lati kọ awọn nkan wọnyi silẹ ko ṣa dede kọ nkan ti o ko si wọn lọkan; Ẹmi Ọlọrun funrarẹ ni o tọ wọn lati kọ awọn nkan wọnyi. Idi si niyi ti a ko fi le tunmọ akọsilẹ ọrọ Ọlọrun kankan pẹlu ọpọlọ wa lasan; a nilo lati jẹ ki ọrọ rẹ tunmọ ara rẹ. Aijẹbẹ, o di dandan ki a gbe nkan gbagi.
Wayi o, Peteru wa fẹ ki o ye wa pe ko ki i ṣe gbogbo awọn wolii igbaani naa ni wolii Ọlọrun lotitọ; awọn wolii eke naa wa ni asiko naa pẹlu. Awọn wolii eke yi naa si jade lati aarin awọn eniyan Ọlọrun. Ki wa ni eyi n kọ wa? Akọkọ ni pe, ti awọn eke wolii ba wa ni asiko awọn wolii Ọlọrun igbaani, a le reti ki wọn wa laarin awa naa, paapaa-julọ ninu awọn ijọ wa. Eyi si ni Peteru fẹ ki o ye wa ni ori ikeji lẹta yi. O fẹ ki a mọ wipe bi awọn eke ojiṣẹ Ọlọrun ṣe wa ni igbaani naa ni wọn tun wa loni pẹlu. A wa nilo lati mọ bi a ṣe le da wọn mọ, ki a ba a le yago fun wọn. Aijẹbẹ, wọn yoo pa igbagbọ wa lara.
Ẹ wa jẹ ka kọkọ wo diẹ lara nkan ti Peteru sọ nipa eyi:
“Ṣugbọn awọn wolii eke wa laarin awọn eniyan naa pẹlu, gẹgẹ bi wọn olukọni eke yoo ti wa laarin yin. Wọn yoo yọ kẹlẹ mu ẹkọ odi ati egbe tọ yin wa, ani ti yoo ṣẹ Oluwa ti o ra wọn pada, wọn o si mu iparun ti o yara kankan wa sori ara wọn. Ọpọlọpọ ni yoo si maa tẹle ọna itiju wọn, ti wọn yoo si mu ki ọna otitọ di isọrọ-odi si. Ninu iwa wọbia wọn, awọn ẹlẹkọ odi wọnyi yoo maa rẹ ẹ yin jẹ nipa itan asan. Idajọ ẹni ti ko falẹ lati igba yii wa ati iparun wọn ti ko si toogbe.” (2Pétérù 2:1-3)
Ṣe o ri bayẹn? Awọn wolii eke wa ni aye igbaani, bi awọn olukọ eke yoo ṣe wa ni aarin wa loni. Nitorina, ko ma ṣe wa ni kayefi rara ti a ba n ri awọn wolii, alufa, apọsiteli ati ajinyinrere eke loni. Ọrọ Ọlọrun ti sọ wipe o di dandan ki wọn wa ninu ijọ. Bawo wa ni a ṣe le da wọn mọ? Peteru, ninu lẹta yi mẹnuba melokan lara awọn nkan ti yoo fi awọn olukọni eke ti o le wa ni aarin ijọ han. Akọkọ lara wọn ni ẹkọ odi ati ẹkọ egbe?
Ki ni ẹkọ odi ati egbe? Ẹkọ odi ati egbe ni oniruuru ẹkọ ti ko wa ni ibamu pẹlu gbogbo otitọ Iwe Mimọ ti a gbe le wa lọwọ. Si wa wo o, ko ki i ṣe gbogbo igba ni ẹkọ odi ati egbe ma n fi gbogbo ara tako otitọ. Igba miran wa ti awọn ẹkọ yi yoo fi ara pẹ otitọ tabi ki wọn jẹ adalu otitọ ati irọ. Boya o wa tako otitọ kedere ni tabi o fi ara pẹ otitọ, ẹkọ odi ati egbe ni, Yoo si ṣe igbagbọ ẹnikẹni ti o ba tẹwọgba ni ijamba.
Apẹrẹ ẹkọ odi ati egbe ni awọn ẹkọ ti o n gbe iṣẹ ọwọ awọn eniyan leke igbagbọ ninu Kirisiti Jesu gẹgẹ bi ọna si igbala. Ṣe Kirisitiẹni ko yẹ ki o ni iṣẹ rere ni? O yẹ! Ọlọrun tilẹ tun wa da lati ma ṣiṣẹ rere ni (Éfésù 2:10). Amọ ko si ibi ti Ọlọrun ti sọ fun wa pe iṣẹ rere wa ni yoo gba wa la. Nitorina, ẹkọ yowu ti o ba n polongo iṣẹ rere tabi iṣẹ isin tabi ipọnra-ẹni-loju gẹgẹ bi ọna si igbala jẹ ẹkọ eke ati egbe. A si gbọdọ yẹra fun irufẹ awọn ti wọn ba n kọ ọ. (Wo: Galatia 5:1-12; Kólósè 2:16-23)
Yatọ si awọn nkan ti a mẹnuba gẹgẹ bi apẹrẹ ẹkọ odi ati egbe wọnyi, ẹkọ yowu ti o ba n kọ awọn eniyan lati ri oore-ọfẹ Ọlọrun gẹgẹ bi ominira lati ma ṣe ohun ti o ba wu wọn jẹ ẹkọ eke ati odi. Awọn ẹkọ ti o n dari awọn eniyan sinu iṣẹ oṣo ati iṣẹ ajẹ nkọ? Ẹkọ odi ati egbe ni awọn wọnyi naa. A si gbọdọ kiyesi awọn ti o ba n kọ irufẹ ẹkọ wọnyi ki a ba a le yẹra fun wọn. (Wo: Gàlátíà 5:13; 1Pétérù 2:16; Júúdà 4)
Peteru wa tẹsiwaju lati jẹ ki o ye wa ọna ti awọn olukọni eke wọnyi ṣe ma n mu ẹkọ eke wọ aarin awọn ọmọ Ọlọrun. O ni nṣe ni wọn ma n yọkẹlẹ mu wọn wọle. Eyi jasi pe awọn naa yoo darapọ mọ awọn ọmọ Ọlọrun gẹgẹ bi ẹni ti o ti di atunbi nitootọ ati olufarasin Kirisiti Jesu. Ki a si ranti pe Jesu ti kẹ ki o ye wa pe Satani ma n yọ kẹlẹ fun irugbin awọn ọmọ tirẹ sinu aye ati sinu ijọ Ọlọrun (Mátíù 13:24-30&.36-43). Ṣugbọn, bopẹ-boya, irufẹ eniyan ti wọn jẹ yoo bẹrẹ si ni farahan.
Lọna wo? Wọn yoo ma wu iwa idọti pẹlu ainitiju. Ekeji, iwa wọbia, irọ pipa ati itan asan siṣọ ko ni ja mọ nkankan loju wọn. Ọpọ eniyan ni wọn yoo si wa ko tira ninu awọn iwa eeri yi. Nitorina, ti a ba ri ọpọ tabi ọgọrọ eniyan ti o n wọ tọ awọn oniwasu kan lọ, ki a ma kanju sọ wipe Ọlọrun ni o n ṣiṣẹ. Ki a kọkọ farabalẹ wo irufẹ ẹkọ ti wọn n kọ ati iwa ti wọn wu. Idi si ni pe o le jẹ wipe idi ti ọpọ ṣe n wọ tọ wọn nipe iṣẹ ọwọ wọn rọ wọn lọrun nitoripe o lodi si ifẹ Ọlọrun.
Wayi o, ki Peteru to tẹsiwaju lati fun wa ni awọn apẹrẹ miran ti o le jẹ ki a da wọn oniwaasu ati adari ijọ eke mọ, o jẹ ki o ye wa daju pe idajọ Ọlọrun di dandan ki o wa sori awọn olukọni eke wọnyi. O tilẹ jẹ ki o ye wa pe idajọ Ọlọrun lori wọn ko ni sun rara; nṣe ni yoo wa sori wọn ni kankan. O si wa sọ awọn nkan wọnyi lati jẹ ki a mọ daju pe awọn olukọni, ajiyinyere, wolii, alufa ati apọsiteli eke ko ni lọ lalai jẹ iya iṣẹ ibi wọn lẹkunrẹrẹ:
“Nitori pe bi Ọlọrun ko ba da awọn angẹli si nigba ti wọn ṣẹ, ṣugbọn ti o sọ wọn si isalẹ ọrun apaadi ti o s fi wọn sinu ọgbun okunkun biribiri ninu ifipamọ titi de idajọ. Bi oun ko si da aye igbaani si, nigba ti o mu ikun omi wa sori aye awọn alaiwa-bi-Ọlọrun, ṣugbọn o pa Noa mọ, oniwaasu ododo, pẹlu awọn ọmọ meje miiran. Ti o sọ awọn ilu Sodomu ati Gomorra di eeru, nigba ti o fi iparun patapata da wọn lẹbi, ti o fi wọn ṣe apẹẹrẹ fun awọn ti yoo jẹ alaiwa-bi-Ọlọrun. Ti o si yọ Lọti olootitọ eniyan, ẹni ti iwa ẹgbin awọn eniyan lailofin ba ninu jẹ; (nitori ọkunrin olootitọ naa bi o ti n gbe aarin wọn, ti o n ri, ti o si n gbọ, lojoojumọ ni iwa buburu wọn n ba ọkan otitọ rẹ jẹ). Bi o ba ri bẹẹ, Oluwa mọ bi a ti n yọ awọn ẹni iwa-bi-Ọlọrun kuro ninu idanwo ati bi a ti n pa awọn alaiṣootọ mọ fun ọjọ idajọ nigba ti wọn yoo tẹsiwaju ninu ijiya ẹṣẹ wọn.” (2Pétérù 2:4-9)
Apẹrẹ mẹta wo ni Peteru fun wa nibiyi lati mu un da wa loju pe ijiya n bọ fun awọn oniwaasu eke ati awọn ti o ba n tẹle wọn? Akọkọ, o fun wa ni apẹrẹ awọn angẹli Ọlọrun ti wọn ṣubu ṣinu ẹṣẹ, eyi ti a mẹnuba ranpẹ ninu iwe Jẹnẹsisi, ori ikẹfa. O si jẹ ki o ye wa pe Ọlọrun gbe awọn angẹli wọnyi de lẹyin iṣubu wọn titi akoko idajọ yoo fi de. Ekeji, o fun wa ni apẹrẹ idajọ ikun omi lori awọn eniyan ni igba aye Noa. Bi a ko tilẹ mọ iye awọn ti o wa lorilẹ aye ni asiko yi, daju-ṣaka ni pe awọn mẹjọ pere ni ko ba ikun omi lọ lara wọn, nigba ti idajọ Ọlọrun wa sori wọn. Ẹkẹta, o fun wa ni apẹrẹ idajọ Ọlọrun ti o wa sori Sodomu, Gomora ati awọn ilu ti o yi wọn ka ni asiko Lọọti. Gbogbo awọn olugbe awọn ilu wọnyi ni Ọlọrun parun nitori ẹṣẹ wọn, yatọ si Lọti ati idile rẹ.
Nitorina, ki a ma wo wipe Ọlọrun ko ri awọn oniwaasu eke ti wọn wa ninu ijọ Ọlọrun kaakiri agbaye loni. O kuku ri wọn. O si di dandan ki O ṣe idajọ wọn ni asiko ti o yẹ. Awa wa ni ki a kiyesara, ki a ma ba kopa ninu idajọ wọn nipa titẹle ọna itiju, ọna ti o n ko ẹrẹ ba orukọ Ọlọrun, ti wọn n tẹle.
Ki a wa ma ba ṣe aṣiṣe ni titẹle awọn eke oniwaasu wọnyi, Peteru tẹsiwaju lati ba wa sọrọ si lori awọn ọna ti a le gba da wọn mọ ati ewu ti o wa ninu ki a tẹle wọn. Wo awọn nkan ti o sọ:
“Ṣugbọn paapaa awọn ti o n tọ ẹran-ara lẹyin ninu ifẹkufẹẹ iwa eeri, ti wọn si n gan awọn ijoye. Awọn ọdaju ati agberaga, wọn ko bẹru lati sọrọ ẹgan si awọn ẹni ogo. Bẹẹ ni awọn angẹli bi wọn ti pọ ni agbara ati ipa to o ni, wọn ko da wọn lẹjọ ẹgan niwaju Oluwa. Ṣugbọn awọn wọnyi, bi ẹranko igbo ti ko ni ero, ẹranko sa a ti a da lati maa mu pa, wọn n sọrọ ẹgan ninu ọrọ ti ko ye wọn, a o pa wọn run patapata ninu ibajẹ ara wọn. Wọn yoo gba ibi pada bi ibi ti wọn ṣe. Oye igbafẹ ti wọn ni lati maa jẹ adun aye. Wọn jẹ abawọn ati abuku, wọn n jaye ninu ifẹkufẹẹ wọn nigba ti wọn ba n jẹ aṣe pẹlu yin. Oju wọn kun fun pansaga, wọn ko si dẹkun ẹṣẹ dida; wọn n tan awọn ti ọkan wọn ko fi ẹsẹ mulẹ jẹ; awọn ti wọn ni ọkan ti o yege ninu wọbia, ọmọ egun, ni wọn. Wọn kọ ọna ti o tọ silẹ, wọn si ṣako lọ, wọn tẹle ọna Balaamu ọmọ Beori, ẹni to fẹran ere aiṣododo. Ṣugbọn a ba a wi nitori irekọja rẹ, odi kẹtẹkẹtẹ fi ohun eniyan sọrọ, o si fi opin si iṣiwere wolii naa. Awọn wọnyi ni kanga ti ko ni omi, ikuukuu ti ẹfuufu n gba kiri, awọn ẹni ti a pa okunkun biribiri mọ de titi lae. Nitori igba ti wọn ba n sọrọ ihalẹ asan, ninu ifẹkufẹẹ ara, wọn a maa tan awọn ti wọn fẹrẹ ma ti i bọ tan kuro lọwọ awọn ti wọn wa ninu iṣina. Wọn a maa ṣe ileri ominira fun wọn, nigba ti awọn paapaa jẹ ẹru idibajẹ; nitori eniyan ti di ẹru ohunkohun ti o ba ṣe ọga rẹ. Lẹyin ti wọn ba ti yọ tan kuro ninu eeri aye nipa mimọ Oluwa ati Olugbala wa Jesu Kirisiti, bi wọn ba si tun fi ara ko o, ti a si ṣẹgun wọn, igbẹyin wọn a buru ju ti iṣaaju lọ. Nitori iba san fun wọn, ki wọn ma mọ ọna ododo, ju pe lẹyin ti wọn mọ ọn tan, ki wọn yipada kuro ninu ofin mimọ ti a fi fun wọn. Owe otitọ naa ṣẹ si wọn lara, “Aja tun pada si eebi ara rẹ; ati ẹlẹdẹ ti a ti wẹmọ tun pada n yiraa ninu ẹrọfọ.”” (2Pétérù 2:10-22)
Ki ni awọn nkan ti a ri tọkasi ninu ọrọ Peteru nibiyi lori awọn oniwaasu eke? Akọkọ, a ri wipe agberaga ni wọn. Ninu igberaga wọn, wọn a si ma sọrọ odi si awọn ẹda-airi, awọn ọrọ ti o ju ẹnu wọn lọ, awọn ọrọ ti awọn angẹli mimọ Ọlọrun gan ko le e sọ. Fun apẹrẹ, a ri awọn ti o ma n gbe Satani ṣepe tabi pe ni oniruuru orukọ. Yatọ si aimọkan-mọkan, nkan miran ti o tun ma n ṣokunfa irufẹ awọn nkan wọnyi ni igberaga. Ti a ba si ti ri awọn ti o n ṣe bi eyi, ki a mọ wipe ko si ẹni ti o jọ wọn loju – agberaga ni wọn. A si gbọdọ yago fun ati awọn ati nkan ti wọn n pe ni iṣẹ-iransẹ wọn.
A tun ri wipe ọdaju, wọbia ati oniṣekuṣe ni awọn wọnyi. Nitorina, ko si nkan ti wọn ko le ṣe lati ni owo ati ọla, lati wa ni ipo atata ati lati tẹ ifẹkufẹ wọn lọrun. Lotitọ, oniwaasu ni wọn n pe ara wọn. Amọ, ti a ba ṣi wa loju tabi ni anfaani lati ri awọn iwa ibajẹ ti o wa lọwọ wọn, ẹru yoo ba wa. Sibẹsibẹ, awọn wọnyi a ma ṣogo ninu iwa eeri wọn. Abalajọ ti Peteru ṣe pe wọn ni àgbá ofifo ati ẹru ẹṣẹ.
Lotitọ, awọn naa a ma ṣe ileri ominira ninu kuro lọwọ eṣẹ ati kuro lọwọ agbara eṣu fun awọn ti o ba n tọ wọn wa. Ṣugbọn garawa ofifo, ẹru eṣu ati ẹṣẹ ni awọn funralara wọn jẹ. Bawo wa ni wọn ṣe le fun ẹnikẹni ni ominira? Ko le e ṣeeṣe. Ayafi ti wọn yoo ba tun ba aye awọn ti o n tọ wọn wa jẹ si. Apẹrẹ eyi si pọ jantirẹrẹ, apẹrẹ awọn ti a ba aye wọn jẹ ninu ijọ Ọlọrun nipasẹ awọn ti wọn n pe ni adari wọn.
Peteru wa pari ọrọ rẹ lori awọn wọnyi nipa sisọ wipe iba san ki wọn ma mọ Kirisiti rara ju pe ki wọn mọ ọn lọ, ki aye wọn si tun wa ko sinu ide eṣu ati ẹṣẹ. Okunkun birimu-birimu ni yoo jẹ ile-ayeraye irufẹ awọn wọnyi ati awọn ti o ba n tẹle wọn.
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Bi a ti ṣe ni awọn ojiṣẹ Ọlọrun olotitọ naa ni awọn ti o jẹ eke wa. Nitorina, a nilo lati kiyesi awọn ikilọ ti a fun wa ninu bibeli lori bi a ti ṣe le mọ awọn eke wọnyi, ki a si yago fun wọn. A o si wa ri wipe Peteru ko sọ nkankan nipa bi awọn wọnyi ṣe n ṣe iṣẹ iyanu si rara. Dipo eyi, irufẹ iwa ati eso ti aye wọn n so ni o sọ wipe ki a kiyesi. Idi si ni pe awọn eniyan le lo iṣẹ-oṣo tabi ọgbọn arekereke lati ṣe iṣẹ́-àrà tabi iṣẹ iyanu. Ṣugbọn ti ko ba si ododo Kirisiti ninu wọn, wọn ko ni le fi so eso. Ẹnikẹni ti ko ba si ma a so eso ododo Jesu Kirisiti ko si lara awọn tirẹ, bi o ti wu ki o pọ ni iṣẹ iyanu ati iṣẹ ara to ati bi o ti wu ki o ma polongo Jesu to (Mátíù 7:15-20). Nitorina, a gbọdọ yago fun iru wọn, ki a ma ba tipasẹ wọn sọ igbagbọ wa di igbagbe.
ÌBÉÈRÈ
– Awọn ọna wo ni ẹkọ yi ṣe ba nkan ti o n lọ ninu ijọ loni mu?
– Ki ni o ṣe pataki si ọ julọ ninu ẹkọ yi?
Láti ọwọ́ Johnson O. Lawal
Copyright © 2025 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)
ÀKỌ́RÍ: 2PÉTÉRÙ 1-IṢU ÀTẸNUMỌ́ | ÀYỌKÀ: 2PÉTÉRÙ 1:1-21 | ỌJỌ́RÚ 23, IGBE 20 25
ÀKỌ́SÓRÍ: “Nitori naa, emi o maa ran yin leti awọn nnkan wnọyii nigbagbogbo, bi o tilẹ jẹ pe ẹyin ti mọ wọn, ti ẹṣẹ yin si mulẹ ninu otitọ ti ẹ ni bayii.” (2Pétérù 1:3)
Ọ̀RỌ̀ ÌSÀÁJÚ
Lẹta Keji Peteru si awọn eniyan Ọlọrun ni a fẹ bẹrẹ si ni gbe yẹwo ninu awọn ẹkọ bibeli wa ni ọṣẹ yi ati awọn eyi ti o n bọ. Bi a si ti ṣe ri ninu lẹta naa, iṣẹ iranṣẹ apọsiteli yi ti n wa si opin ni asiko ti o kọ ọ. Bi o tilẹ jẹ wipe a le ma le e fi ọwọ sọya lori asiko ti o kọ ọ tabi ibi ti o wa ni asiko ti o kọ ọ, nkan ti o ṣe pataki julọ ni idi ti o ṣe kọ ọ ati awọn ẹkọ ti a le ti ara rẹ kọ. Idi wo si ni o ṣe kọ ọ? Bi a ti ṣe ri nu ẹsẹ akọsori wa, o kọ ọ lati ran awọn ọmọ Ọlọrun leti awọn nkan ti wọn ti mọ nipa igbagbọ ninu Kirisiti Jesu, ki wọn ba a le duro ṣinṣin ninu wọn. Awọn Yoruba bọ, wọn a ni, “Iṣu atẹnumọ ki i jona.” Eyi tunmọ si pe ti a ba n pe akiyesi eniyan leralera si ọrọ kan, yoo ṣoro fun ẹni naa lati gbagbe rẹ. Bẹẹ gẹgẹ naa ni o si ṣe ri pẹlu ọrọ Ọlọrun. A nilo lati ma pe akiyesi ara wa si awọn nkan ti O sọ fun wa nipa igbagbọ wa ati nipa iduroṣinṣin wa ninu ifẹ rẹ leralera. Aijẹbẹ, o ṣeeṣe ki a gbagbe, ki ọjọ Oluwa si de ba wa lojiji, lalai wa ni imurasilẹ. Nitorina, lẹta Peteru keji da lori riran awọn ọmọ Ọlọrun leti awọn nkan ti wọn nilo lati gbajumọ, ki wọn ba a le wa ni imura silẹ de ọjọ Oluwa ni ailabawọn.
KÒ KÌ Í ṢE ÌTÀN ASÁN
Wayi o, ni ori ikinni lẹta yi, Peteru, lẹyin ikini rẹ, sọrọ lori nkan mẹta gbogi. Akọkọ, o sọrọ lori pataki ki a ṣe amulo gbogbo ipese Ọlọrun fun wa lati gbe igbe aye iwa-bi-Ọlọrun ati lati ṣe ara wa yẹ fun ile-ogo rẹ. Ekeji, o sọrọ lori imurasilẹ rẹ lati lọ ba Jesu Kiristi Oluwa wa ni ile. Ẹkẹta, o jẹ ki o ye wa pe igbagbọ wa ninu Kirisiti ko ki i ṣe lori itan asan bi ko ṣe lori awọn nkan ti o ṣẹlẹ lotitọ, ti o si tun ni ẹlẹri.
Ẹ wa jẹ ki bẹrẹ si ni gbe awọn nkan wọnyi wo lẹyọ kọọkan, bẹrẹ pẹlu iyanju rẹ si wa lati ma fi gbogbo igba ṣe amulo awọn ipese Ọlọrun fun wa lati gbe igbe aye iwa-bi-Ọlọrun ni inu aye idibajẹ yi. Iwọ naa wo nkan ti o sọ:
“Simoni Peteru, iransẹ ati apọsteli Jesu Kirisiti, Si awọn ti o gba iru iyebiye igbagbọ kan naa pẹlu wa ninu ododo Ọlọrun wa ati ti Jesu Kirisiti Olugbala. Ki oore-ọfẹ ati alaafia maa bi si i fun yin ninu imọ Ọlọrun ati ti Jesu Oluwa wa. Bi agbara rẹ bi Ọlọrun ti fun wa li ohun gbogbo ti iṣe ti iye ati ti iwa-bi-Ọlọrun, nipa imọ ẹniti o pe wa nipa ogo ati ọlanla rẹ: Nipa eyiti o ti fi awọn ileri rẹ ti o tobi pupọ ti o si ṣe iyebiye fun wa: pe nipa iwọnyi ni ki ẹnyin ki o le di alabapin ninu iwa Ọlọrun, nigbati ẹnyin ba ti yọ kuro ninu ibajẹ ti mbẹ ninu aye nipa ifẹkufẹ. Ati nitori idi eyi, ẹ maa ṣe aisimi gbogbo, ẹ fi iwa rere kun igbagbọ, ati imọ kun iwa rere; ati airekọja kun imọ; ati suuru kun airekọja; ati iwa-bi-Ọlọrun kun suuru. Ati ifẹ ọmọnikeji kun iwa-bi-Ọlọrun; ati ifẹni kun ifẹ ọmọnikeji. Nitori bi ẹyin ba ni nnkan wọnyi ti wọn ba si pọ, wọn ki yoo jẹ ki ẹ ṣe ọlẹ tabi alaileso ninu imọ Oluwa wa Jesu Kirisiti. Ṣugbọn ẹni ti o ba ṣe alaini nnkan wọnyi, ko le riran ri okeere, o fọju, o si ti gbagbe pe a ti wẹ oun nu kuro ninu ẹsẹ rẹ atijọ. Nitori naa, ara ẹ tubọ maa ṣe aisimi lati sọ ipe ati yiyan yin di dajudaju, nitori bi ẹyin ba n ṣe nnkan wọnyi, ẹyin ki yoo ṣubu. Nitori bayii ni a o pese fun yin lọpọlọpọ lati wọ ijọba ainipẹkun ti Oluwa ati Olugbala wa Jesu Kirisiti.” (2Peteru 1:1-11)
Bi a ti ṣe ri ninu ọrọ Peteru wọnyi, irufẹ igbagbọ kan naa ni awa ati awọn apọsiteli igbaani ni. Iha ti a ba wa kọ si gbigbe igbagbọ naa ro ati lilo ni ibamu pẹlu ọrọ Ọlọrun ni yoo sọ bi yoo ti ṣe ṣiṣẹ fun wa si. Siwaju si, apọsiteli yi jẹ ki o ye wa pe nipasẹ agbara Ọlọrun a ti pese ohun gbogbo ti a nilo fun igbayegbadun wa ati iwa-bi-Ọlọrun fun wa. Ki wa ni o ku wa ku? Ki a bẹrẹ si ni gbe igbesẹ lati mọ awọn ipese Ọlọrun fun wa ati lati ṣe amulo wọn.
Idi si ni yi ti Peteru ṣe sọ fun wa pe ki a bẹrẹ si ni lepa ni igba gbogbo lati pọ si ni siso eso igbagbọ, imọ-Ọlọrun, iwa rere, airekọja, suuru ati ifẹ. O si jẹ ki o ye wa pe, ti a ba n pọ si ninu awọn nkan wọnyi, imọ Ọlọrun ti a ni ko ni ja si ofo. Ọpọ ni o jẹ wipe imọ Ọlọrun ti wọn ni ko ja mọ nkankan. Idi si ni pe imọ yi ko yi aye wọn pada, ki o sọ wọn di ẹni ọtun ni iwa ati ni iṣe. Nitorina, a nilo lati mọ wipe ojuṣe wa ni lati lepa lati ṣe amulo agbara Ọlọrun lati pọ si ni isesorere. Aijẹbẹ, bi igba ti a ti gbagbe pe a di atunbi ni a o ṣe ma gbe ile aye wa. Awọn ti o ba wa n fi igba gbogbo mura lati fi idi ipe ati yiyan wọn nipasẹ Kiristi mulẹ nipa gbigbe igbe aye iwa-bi-Ọlọrun ni ko ni lailai ṣubu. Yatọ si eyi, awọn wọnyi naa ni a o ṣi ilẹkun ainipẹkun Ọlọrun fun pẹlu ayẹsi lọpọlọpọ.
Nkan ekeji ti Peteru mẹnuba ni ori kinni iwe yi, bi mo ti ṣe sọ tẹlẹ, ni i ṣe pẹlu imurasilẹ rẹ lati pari iṣẹ iranṣẹ rẹ ati lati pade Jesu Oluwa wa. Iwọ naa wo nkan ti o sọ lori eyi:
“Nitori naa, emi o maa ran yin leti awọn nnkan wọnyi nigba gbogbo, bi o tilẹ jẹ pe ẹyin ti mọ wọn, ti ẹsẹ yin si mulẹ ninu otitọ ti ẹ ni bayii. Emi si ro pe o tọ lati maa mu wọn wa si iranti yii. Bi emi ti mọ pe, bibọ agọ ara mi yii silẹ ku si dẹdeẹ, ani, bi Oluwa wa Jesu Kristi ti fihan mi. Emi o si maa ṣaapọn pẹlu, ki ẹyin le maa ranti nnkan wọnyi nigba gbogbo lẹyin iku mi.” (2Pétérù 1:12-15)
Ki ni a ri nibiyi? Akọkọ ni pe Jesu ti fi han Peteru wipe asiko iku rẹ ti sunmọ etile. Eyi si n jẹ ki o ye wa pe ko ki i ṣe nkan ti o tọna ni ki Kirisitiẹni kan ṣa dede ku, lalai ṣe wipe a ti pese ọkan rẹ silẹ fun ipadabọwasile rẹ. Kirisitiẹni ti o ba kan ṣa dede ku ko fi taratara fi ọkan ba Ọlọrun rin. Ti o ba n fi ọkan ba Ọlọrun rin, a o ti fi han pe asiko rẹ ti n to, ki o ba le murasilẹ, ki o si ṣe ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu irin ati iṣẹ-iranṣẹ rẹ ni aṣepe.
Nkan ekeji ti a ri ninu nkan ti Peteru sọ ninu awọn ẹsẹ lẹta rẹ yi ni pe o ṣetan lati lo asiko ti o kun fun un lati ma a ran awọn ọmọ Ọlọrun leti gbogbo awọn nkan ti yoo jẹ ki wọn wa ni imurasilẹ de bibọ Jesu. Eyi ko wa jasi pe a nilo lati sun mọ bebe iku ki a to ma ran ara wa leti pe ki a wa ni imurasilẹ de bibọ Jesu. Dipo bẹẹ, nkan ti eyi n kọ wa ni pe a gbọdọ kọ bi a ṣe n ṣe amulo asiko yowu ti Ọlọrun ba fun wa lati ṣe ohun gbogbo ti a mọ gẹgẹ bi ifẹ rẹ. Aijẹbẹ, alẹ́ le lẹ mọ wa lẹnu iṣẹ ti a n ṣe, ki a si ma ni anfaani lati pari rẹ. (Wo: Jòhánù 9:4)
Siwaju si, nkan kẹta gbogi ti Peteru mẹnuba ni ori kinni iwe yi ni wipe igbagbọ wa ninu Kirisiti Jesu ko da lori itan asan. Wo nkan ti o sọ lori eyi:
“Nitori ki i ṣe bi ẹni ti o n tọ itan asan lẹyin ti a fi ọgbọnkọgbọn la silẹ, nigba ti awa sọ fun yin ni ti agbara ati wiwa Jesu Kiristi Oluwa, ṣugbọn ẹlẹrii ọlanla rẹ ni awa jẹ. Nitori ti O gba ọla ati ogo lati ọdọ Ọlọrun Baba, nigba ti iru ohun yii fọ si i lati inu ogo nla naa wa pe, “Eyi ni ayanfẹ ọmọ mi, ẹni ti inu mi dun si gidigidi.” Awa pẹlu si gbọ ohun yii ti o ti ọrun wa nigba ti awa wa pẹlu rẹ ni ori oke mimọ naa. Awa si ni ifẹsẹmulẹ ọrọ awọn wolii dunjudunju si i, eyi ti o yẹ ki ẹ kiyesi gẹgẹ bi fitila to n mọlẹ nibi ti okunkun gbe wa, titi ilẹ yio fi mọ, ti irawọ owuro yoo si yọ lọkan yin. Ju gbogbo rẹ lọ, ki ẹ ni oye yii pe ko si asọtẹlẹ iwe mimọ kankan ti o waye nipa itumọ wolii fun rara rẹ. Nitori asọtẹlẹ kan ko ti ipa ifẹ eniyan wa ri; sugbọn awọn eniyan n sọrọ lati ọdọ Ọlọrun bi a ti n dari wọn lati ọwọ Ẹmi Mimọ wa.” (2Pétérù 1:16-21)
Ki ni a ri nibiyi? Ohun naa ni pe gbogbo awọn nkan ti a n fi waasu nipa Jesu ni o jẹ otitọ ati ododo. Gbogbo awọn nkan ti a kọ silẹ nipa igbesi aye rẹ ni o ni ẹlẹrii. Peteru tilẹ jẹ ki o ye wa pe oun ati awọn kan wa nibẹ nigba ti Ọlọrun funrarẹ jẹri pe Ayanfẹ ọmọ Oun ni Jesu n ṣe. A si ri akọsilẹ awọn nkan wọnyi naa ninu awọn iwe awọn ajinyinrere bi Matiu, Maaku ati Luuku. Nitorina, bi o tilẹ jẹ wipe awọn ẹ̀ṣìn wa ti a gbe kalẹ lori itan asan pẹlu ọgbọn ẹwẹ, ọgbọn arekereke awọn eniyan, itan igbesi aye Jesu, iku rẹ, ajinde rẹ ati igbasoke rẹ ko da lori itan asan. Nitorina, igbagbọ wa ninu rẹ ko ki iṣe ofo. (Wo: Mátíù 17:1-13; Máàkù 9:1-13; Lúùkù 9:28-36)
Yatọ si eyi, Peteru tun jẹ ki o ye wa pe ọpọlọpọ akọsilẹ awọn wolii ni a ri ninu iwe mimọ ti o n tọka si igbe aye Jesu, iku rẹ, ajinde rẹ ati igbasoke rẹ, fun irapada awọn eniyan ati ifilọlẹ ijọba ainipẹkun Ọlọrun. O wa n jẹ ki o ye wa pe ọrọ awọn wolii yi gan ṣe pataki fun wa lati kiyesi ju iriri yowu ti oun tabi ẹnikẹni le ni nipa Jesu lọ. Eyi jasi pe a gbọdọ mu ọrọ Ọlọrun ti a ti ọwọ awọn wolii rẹ igbani kọ silẹ fun wa ni pataki ju iran, ifarahan ẹmi tabi ala ti a le fun ẹnikẹni nipasẹ Jesu lọ. Idi si ni pe awọn wolii yi ko kọ awọn nkan ti wọn kọ silẹ fun wa lati inu ọpọlọ wọn. Ẹmi Ọlọrun ni o dari wọn lati kọ wọn silẹ. Nitorina, ti oye nkan ti wọn ba kọ silẹ yoo ba ye wa, a ni lati wo wọn ni ibamu pẹlu ohun gbogbo ti Ẹmi Ọlọrun n sọ fun wa ninu Iwe mimọ. Aijẹbẹ, a o gbe gbagi.
Ni kukuru, koko nkan ti Peteru n sọ fun wa ni pe ọrọ Iwe mimọ ni a gbọdọ ma fi gbogbo igba gbe leke. Eyi tunmọ si pe a ko gbọdọ kọbiara si iran, ala, ifarahan angẹli tabi isọtẹlẹ ti ko ba wa ni ibamu pẹlu ọrọ Iwe mimọ. Yatọ si eyi, ti a ko ba fẹ ṣi ara wa lọna pẹlu ọrọ Iwe mimọ pẹlu, a nilo lati jẹ ki o ma fi igba gbogbo ṣe alaye ara rẹ.
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Peteru kọ lẹta rẹ akọkọ lati ma a fi asiko rẹ ti o ku laye ran awọn ọmọ Ọlọrun leti awọn nkan ti wọn nilo lati kiyesi lati wa ni imurasilẹ fun dide Jesu. Ki wa ni awa n fi asiko wa ti o ku laye, bi o ti wu ki o pọ tabi kere to, ṣe?
ÌBÉÈRÈ
– Awọn ọna wo ni o ro wipe ẹkọ yi gba wulo fun ọ ninu irinajo igbagbọ rẹ?
Lati ọwọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2025 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)
ÀKỌ́RÍ: ÀSÌKÒ ÌDÁJỌ́ LE È Yàtọ̀ | ÀYỌKÀ: ÁBÁKÚKU 2:1-17 | ỌJỌ́RÚ 26, ẸRẸ́NÀ 2025
ÀKỌ́SÓRÍ: “Emi yoo duro lori ibusọ mi lati maa woye. Emi yoo si gbe ara mi ka ori alore. Emi yoo si sọ lati gbọ ohun ti yoo sọ fun mi ati esi ti emi yoo fun ẹsun yii nigba to ba n ba mi wi.” (Ábákúkù 2:1)
Ọ̀RỌ̀ ÌSÀÁJÚ
Ninu ẹkọ ti a kọ siwaju ninu iwe Abakuku, ori ikinni, a ri awọn ibere ti wolii yii bere lọwọ Ọlọrun lori iha ti O kọ si iwa ibi ti o gbilẹ ni awujọ rẹ ati idahun ti Ọlọrun fun un. Eyi si jẹ ki oye ye wa pe ko si igba ti Ọlọrun ko ki i kọbiara si iwa ibi tabi iwa ibajẹ. Gbogbo igba ni O ma n kọbiara si i. Amọ niwọn igba ti aye ba ṣi silẹ fun iṣedari ni ibi gbogbo, bẹrẹ lati inu ẹbi kọọkan lọ, yoo fi aye silẹ fun awọn adari lati ṣe idajọ iwa ibi ati iwa ibajẹ ti o ba n waye ni abẹ iṣakoso wọn. Igba ti wọn ba kọ ti wọn ko ṣe eyi ni aarin asiko ti Ọlọrun fun wọn ni O to le gbe igbesẹ lati ṣe idajọ funrarẹ. Nigba ti O ba si nṣe eyi, ko si ẹnikẹni ti o le sọ ọna ti yoo gba tabi ibi ti idajọ rẹ yoo yọri si. Niti awọn ara Juda asiko wolii Abakuku, awọn ara Babiloni ni Ọlọrun fẹ ẹ lo lati ṣe idajọ iwa ibi ti o wa ni awujọ wọn. Amọ eyi ko tẹ Abakuku lọrun. Ko tẹ lọrun nitoripe o woye pe ko ki i ṣe awọn ti n ṣe alaiṣododo ju wọn lọ ni o yẹ ki Ọlọrun lo lati jẹ wọn niya. Loju tirẹ, eyi ko fi Ọlọrun han gẹgẹ bi olododo. O si fi ehonu rẹ han si Ọlọrun lori eyi. Oun naa si wa da lohun. Idahun yi ni a fẹ wo ninu ẹkọ yi, eyi ti o wa ninu ori ikeji iwe wolii naa.
ÀSÌKÒ ÌDÁJỌ́ LE È YÀTỌ̀
Wayi, ki Ọlọrun to da Abakuku lohun ibere rẹ, oun funrarẹ ti mura silẹ de idahun naa. Wo nkan ti o sọ:
“Lori ile iṣọ mi ni emi o duro, emi o si gbe ara mi ka ori alore, emi o si ṣọ lati ri ohun ti yoo sọ fun mi, ati esi ti emi o fọ, nigba ti a ba n ba mi wi.” (Ábákúkù 2:1)
Njẹ o ri bayẹn? Ọkunrin yi wa ni imurasilẹ lati gbọ ohun ati idahun Ọlọrun. Melo ninu awa ti a n fẹ ki Ọlọrun ma ba wa sọrọ ni a ma n wa ni imurasilẹ fun un lati ba wa sọrọ? Ti a ba lọ si awọn ipade ijọ wa, njẹ a ma n lọ pẹlu imurasilẹ lati gbọ ohun Ọlọrun bi? Ọpọ ninu wa ni a o ti lo ara wa yọ ki a to lọ fun awọn ipade wọnyi. Nigba ti a ba wa de ibẹ, nṣe ni a o ma toogbe tabi sun. A si fẹ ki Ọlọrun ba wa sọrọ. Njẹ eyi yoo ṣeeṣe bi?
Ọpọ ninu wa ni o tun jẹ wipe ẹjọ ni a ma n to ti a ba lọ si ipade awọn ọmọ Ọlọrun. A si n fẹ ki Ọlọrun ba wa sọrọ. Bawo ni yoo ṣe ba wa sọrọ? Bawo ni a ṣe tilẹ fẹ gbọ ohun rẹ ti O ba n ba wa sọrọ? Eyi ko wa mọ pẹlu awọn ipade ijọ wa nikan. Ni aaye ara wa, njẹ a n ka ọrọ Ọlọrun pẹlu ireti ati imurasilẹ pe ki O ba wa sọrọ? Ṣe lori oorun tabi oogbe wa ni yoo ti ba wa sọrọ? Tabi ṣe nibi ti a ti n to ẹjọ tabi wo iran ni asiko ti n ka bibeli ni Ọlọrun yoo ti le ba wa sọrọ?
Koko nkan ti a n sọ ni pe, niwọn igba ti ọkan wa ko ba ti wa ni imurasilẹ fun Ọlọrun lati ba wa sọrọ, bi O tilẹ fẹ ba wa sọrọ, ko si idaniloju pe a o gbọ ohun yowu ti O ba fẹ ba wa sọ. Lati gbọ esi ti Ọlọrun yoo fun Abakuku, o fi ara rẹ si ipo imurasilẹ. Ṣe Ọlọrun si wa ba a sọrọ tabi ko ba sọrọ? Ọlọrun kuku ba a sọrọ. Ọlọrun fun ni idahun ibere rẹ. Iwọ naa wo idahun rẹ:
“Oluwa si da mi lohun, o si wi pe, Kọ iran naa ki o si han lara sileeti, ki ẹni ti o n ka a, le maa sare. Nitori iran naa jẹ ti igba kan ti a yan, yoo maa yara si igbẹyin, ki yoo si ṣeke, bi o tilẹ pẹ, duro de e, nitori ni dide, yoo de, ki yoo pẹ. Kiyesi i, ọkan onigberaga ko duro ṣinṣin ninu rẹ ṣugbọn olododo yoo ye nipa igbagbọ rẹ. Bẹẹ ni pẹlu, nitori ti waini ni ẹtan rẹ, agberega eniyan ni oun, kii si sinmi, ẹni ti o sọ ifẹ rẹ di gbigbooro bi ipo-oku, o si dabi iku, a ko si le tẹ ẹ lọrun, ṣugbọn, o ko gbogbo orilẹ-ede jọ si ọdọ, o si gba gbogbo eniyan jọ si ọdọ rẹ: Gbogbo awọn wọnyi ki yoo ha maa pa owe si i, ti wọn o si ma kọ orin owe si i, wi pe, Egbe ni fun ẹni ti n mu ohun ti ki i ṣe tirẹ pọ si i! Yoo ti pẹ to? Fun ẹni ti n di ẹru ilọnilọwọgba ni ru ara rẹ? Awọn ti o yọ ọ lẹnu ki yoo ha dide lojiji? Awọn ti o wahala rẹ ki yoo ha ji? Iwọ ki yoo ha si di ikogun fun wọn? Nitori iwọ ti ko orilẹ-ede pupọ gbogbo iyoku awọn eniyan naa ni yoo ko ọ; nitori ẹjẹ eniyan ati iwa ipa ilẹ naa, ti ilu naa, ati gbogbo awọn ti n gbe inu rẹ. Egbe ni fun ẹni ti n jẹ ere ijẹkujẹ si ile rẹ, ki o le baa gbe itẹ rẹ ka ibi giga, ki o le baa gba a silẹ kuro lọwọ ibi! Iwọ ti gbimọ itiju si ile rẹ nipa eniyan pupọ, o si ti ṣẹ si ọkan rẹ. Nitori ti okuta yoo kigbe lati inu ogiri wa, ati igi idabuu lati inu opo wa yoo si da a lohun. Egbe ni fun ẹni ti o fi ẹjẹ kọ ilu, ti o si fi aiṣedeede tẹ ilu nla do. Kiyesi i, ti Oluwa awọn ọmọ ogun ha kọ pe, ki awọn eniyan naa maa ṣe laalaa fun ina, ati ki awọn eniyan naa si maa ṣe laalaa lasan? Nitori ti aye yoo kun fun imọ ogo Oluwa bi omi ti bo okun. Egbe ni fun ẹni ti o fi ohun mimu fun aladuugbo rẹ, ti o si fi ọti lile rẹ fun un, ti o si jẹ ki o mu amupara pẹlu, ki iwọ baa e wo ihoho wọn! Itiju yoo bo ọ dipo ogo, iwọ naa mu pẹlu, ki ihooho rẹ ki o le han, aago ọwọ ọtun Oluwa yoo yi pada si ọ, itiju yoo si bo ogo rẹ. Nitori ti iwa ipa ti Lebanoni yoo bo ọ, ati ikogun awọn ẹranko ti o ba wọn ni ẹru, nitori ẹjẹ eniyan ati iwa ipa ilẹ naa, ti ilu naa, ati ti gbogbo awọn ti n gbe inu rẹ.” (Ábákúkù 2:2-17)
Njẹ Ọlọrun ṣe alaye fun Abakuku idi ti O fi fẹ lo awọn ara Babiloni lati ṣe idajọ orilẹ-ede Juda ninu idahun rẹ yi bi? Rara o! Ki ni idi? Idi ni wipe Ọlọrun ko nilo lati ṣe alaye fun ẹnikẹni idi ti O ṣe pinnu lati ṣe idajọ iwa ika ni ọna yowu ti O ba wu. Ṣe Ọlọrun lẹtọ lati ṣe idajọ iwa ika? Bẹẹni! Ki si ni idajọ ti O peye ju fun iwa ika? Iku ni!
Bibeli sọ wipe iku ni ere ẹṣẹ (Róòmù 6:23). Idi si ni yi ti Ọlọrun fi le pa ẹnikẹni nitori ẹṣẹ, bi o ti wu ki ẹṣẹ ẹni naa da bi ẹni ti o kere to. Ti O ba wa ṣaanu fun ẹnikan, ki a ma ṣe ro wipe ẹtọ ẹnikẹni ni lati ri aanu gba. Aanu ko ki i ṣe ẹtọ fun ẹnikẹni – ẹbun ni o jẹ. Ti Ọlọrun ba si kọ ti ko ṣe aanu fun ẹlẹṣẹ, ko ma jẹbi rara. Ti Ọlọrun ba si tun yan ọna yowu ti o wu lati jẹ ẹlẹṣẹ niya, ko ma jẹbi, bẹẹ si ni ko nilo lati ṣe alaye fun ẹnikẹni.
Nitorina, Ọlọrun ko tilẹ gbe igbesẹ tabi tiraka lati ṣe alaye fun Abakuku idi ti Oun fi yan lati lo orilẹ-ede Babiloni, orilẹ-ede awọn abọriṣa, orilẹ-ede awọn ẹlẹṣẹ paraku, lati jẹ awọn eniyan rẹ niya, bi o tilẹ jẹ wipe awọn eniyan rẹ san ju wọn lọ. Dipo eyi, nṣe ni Ọlọrun n jẹ ki o ye Abakuku pe awọn ara Babiloni naa ko ni lọ lalai jiya ẹṣẹ wọn. Otitọ ni pe Oun n lo wọn gẹgẹ bi pasan ibawi fun awọn alaigbọran eniyan rẹ, iyẹn awọn ara Juda. Amọ, o di dandan ki awọn naa jẹ iya gbogbo ẹṣẹ wọn nigba ti asiko ba to.
Amọ ṣa o, asiko ibawi ati idajọ orilẹ-ede Babiloni ko i ti to ni asiko ti Ọlọrun n ba Abakuku sọrọ yi. Nitorina, O sọ fun wipe ko kọ iran idajọ Babiloni silẹ, ki o si jẹ ki o han kedere. Ki ni idi? Akọkọ, idi ni pe ko fẹ ki iran naa ṣoro fun ẹnikẹni lati ka. Ekeji, O fẹ ki ẹnikẹni ti o ba ka iran naa le sare pẹlu rẹ lati fi jiṣẹ fun awọn miran. Ẹkẹta, O fẹ ki awọn eniyan ranti pe Oun ti sọrọ lori idajọ Babiloni ṣaaju ki o to waye.
Ki a ma fọrọgun, nipasẹ iran ti Ọlọrun fun Abakuku gẹgẹ bi idahun si ibere rẹ yi, a ri wipe egbe ni fun gbogbo awọn ti o ba n wuwa ika, ti wọn n fi eru ati ọna aitọ ko ọrọ jọ, ti wọn n fi itajẹsilẹ gbe ara wọn soke tabi ti wọn n tan awọn miran jẹ lati fi wọn ṣe ẹlẹya. Gbogbo nkan ti wọn n ṣe fun awọn miran ni awọn naa yo pada wa jiya rẹ, bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun lo wọn gẹgẹ bi pasan fun awọn alaigbọran. Eyi si ni Ọlọrun fẹ ki o ye Abakuku nipa awọn ara Babilonia. Awọn naa yoo pada di ẹni ilẹ ati ẹni igbagbe nigba ti asiko idajọ Ọlọrun ba de si wọn.
Ọlọrun si tun wa tẹsiwaju lati jẹ ki o ye Abakuku pe gbogbo awọn oriṣa ti awọn ara Babiloni n bọ ko ni le gba wọn la ni ọjọ idajọ Oun. Iwọ naa wo nkan ti a sọ lori eyi:
“Ere kin ni ere finfin ni? Ti oniṣọna rẹ fi gbẹ ẹ; ere dida ati olukọ eke, ti ẹni ti n ṣe iṣẹ rẹ fi gbẹkẹle e lati ma ṣe ere ti o yadi? Egbe ni fun ẹni ti o wi fun igi pe, Ji, fun okuta ti o yadi pe, Dide, oun o kọ ni! Kiyesi i, wura ati fadaka ni a fi bo o yika, ko si si ẹmi kan ninu rẹ. Ṣugbọn Oluwa n bẹ ninu tẹmpili mimọ rẹ; jẹ ki gbogbo aye pa rọrọ niwaju rẹ.” (Ábákúkù 2:18-20)
Eyi wa n jẹ ki o ye wa pe ti awọn eniyan ba ro wipe awọn oriṣa wọn, iṣẹ oṣo wọn tabi iṣẹ ajẹ wọn ni o n jẹ ki wọn rọwọ mu tabi ti ko jẹ ki ajalu de ba wọn tabi ti ko jẹ ki wọn jiya awọn iwa ika wọn, oye ko ye wọn ni. Oye ki ni ko si ye wọn? Oye pe asiko idajọ Ọlọrun lori wọn ko i ti de ni. Ọlọrun si n fi aye ironupiwada silẹ fun wọn ni. Ṣugbọn ni ọjọ ti asiko idajọ wọn ba de, ko si oriṣa, iṣẹ-oṣo tabi iṣẹ-ajẹ ti yoo le gba wọn kuro lọwọ rẹ.
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Ki wa ni ẹkọ fun wa ninu gbogbo eyi? Oun naa ni pe ko si ẹni ti yoo bọ lọwọ idajọ Ọlọrun. Asiko idajọ ẹnikọọkan ni o le yatọ. Nitorina, o ṣeeṣe ki awọn ti iwa wọn dara ju ti wa lọ jẹ iya ẹṣẹ wọn ṣaaju wa. Eyi ko jasi pe Ọlọrun ko ri ti wa ro tabi pe a ti bọ lọwọ idajọ rẹ. A ko le bọ lọwọ idajọ rẹ rara. Asiko ni ko kan i ti to. Nigba ti asiko ba to, o di dandan ki idajọ ti o tọ si wa wa sori wa. Idi niyi ti a fi gbọdọ lo asiko yowu ti Ọlọrun ba fun wa fun ironupiwada lọna ti o peye. Aijẹbẹ, idajọ rẹ di dandan ki o wa sori wa ni asiko rẹ ti a ba kọ lati ronupiwada.
ÌBÉÈRÈ
– Ọna wo ni ẹkọ yi gba fun ọ ni oye idajọ Ọlọrun si i?
Lati ọwọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2025 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)
ÀKỌ́RÍ: SÍBẸ̀ ÈMI Ó LÁYỌ̀ | ÀYỌKÀ: ÁBÁKÚKU 3:1-19 | ỌJỌ́RÚ 02, IGBE 2025
ÀKỌ́SÓRÍ: “Sibẹ, emi o layọ ninu Oluwa, emi yoo si maa yọ ninu Ọlọrun igbala mi.” (Ábákúkù 3:18)
Ọ̀RỌ̀ ÌSÀÁJÚ
Ninu awọn ẹkọ ti a kọ sẹyin ninu iwe Abakuku, a ri itakurusọ ti o waye laarin oun ati Ọlọrun. A ri awọn ibeere ti o bere lọwọ Ọlọrun ati awọn idahun ti O fun un. Ṣe idahun Ọlọrun wa tẹ ẹ lọrun bi? Bi a o ti ṣe ri ni ori ikẹta iwe naa, daju ṣaka ni pe awọn idahun ti Ọlọrun fun wolii yi tẹ ẹ lọrun. Bawo ni a ṣe mọ? A mọ nitoripe, lẹyin idahun ti a fun un, ko bere ibeere miran lọwọ Ọlọrun mọ. Dipo bẹẹ, nṣe ni o bẹrẹ si ni gbadura si i, ti o si tun n kọrin lati yin in. Adura ati ori iyin rẹ si Ọlọrun si ni a fẹ ṣe agbeyẹwo wọn ninu ori ikẹta iwe rẹ ninu ẹkọ yi.
SÍBẸ̀ ÈMI Ó LÁYỌ̀
Wayi o, lẹyin igba ti Ọlọrun da wolii Abakuku lohun tan, oun naa fesi pẹlu orin adura ati iyin lẹnu rẹ. Iwọ naa nkan ti iwe rẹ sọ lori eyi:
“Adura wolii Habakuku gẹgẹ bi sigonoti. Ohun elo orin. Oluwa mo ti gbọ ohun rẹ; ẹru si ba mi fun iṣẹ rẹ Oluwa sọ wọn di ọtun ni ọjọ ti wa, ni akoko tiwa, jẹ ko di mi mọ; ni ibinu, ranti aanu.” (Ábákúkù 3:1-2)
Njẹ o ri bayẹn? Adura Abakuku ni awọn nkan ti a kọ silẹ ni ori ikẹta, eyi ti o pari iwe rẹ. Ki si ni awọn nkan akọkọ ti o bere lọwọ Ọlọrun ninu adura rẹ? Akọkọ, o n fẹ ki Ọlọrun tun awọn iṣẹ iyanu ati igbala ti O ti ṣe sẹyin ṣe ni asiko rẹ. Bi Abakuku ti ṣe sọ, oun ti gburo Oluwa ati agbara rẹ. Bẹni, o ti ka ati gbọ nipa awọn oniruru iṣẹ iyanu ti Ọlọrun ṣe lati gba awọn eniyan rẹ ni Ijibiti ati lọwọ awọn ọta wọn miran. Niwọn igba ti Ọlọrun yi si wa jẹ ọkan naa lana, loni ati titi lailai, Abakuku fẹ ki O tun awọn iṣẹ iyanu igbala ati imupadabọsipo wọnyi ṣe ni asiko tirẹ naa pẹlu. Eyi si n jẹ ki o ye awa naa pe a le gbadura pe ki Ọlọrun tun awọn iṣẹ ara ati iṣẹ iyanu ti O ṣe fun awọn eniyan igbaani ṣe fun awa naa ati laarin awujọ wa.
Yatọ si eyi, Abakuku bẹ Ọlọrun pe ki O ranti pe alaanu ni Oun ninu ibinu rẹ. Eyi jasi pe Abakuku ti gba pe Ọlọrun lẹtọ lati ṣe idajọ awọn eniyan rẹ ni ọna yowu ti O ba wu u. Sibẹsibẹ, o fẹ ki Ọlọrun ṣaanu fun wọn. Alaanu si ni. Nitorina, ko si nkan ti o buru nibẹ ti Abakuku ba bere fun aanu rẹ ni asiko idajọ. A si wa jẹ ki o ye awa naa ti a wa ninu Kirisiti Jesu pe a le sumọ itẹ-aanu Ọlọrun pẹlu igboya lati gba aanu ati oore-ọfẹ rẹ ni asiko yowu ti a ba nilo wọn ninu aye wa (Heberu 4:16). Nitorina, bi a tilẹ ba ara wa tabi awujọ wa tabi orilẹ-ede wa ni abẹ idajọ Ọlọrun, a si ni anfaani lati sunmọ Ọlọrun pe ki O ranti pe alaanu ni Oun, ki O si ṣaanu fun wa ninu idajọ rẹ. (Wo: Ẹ́kísódù 34:5-7)
Lẹyin awọn ọrọ adura yi, Abakuku wa tẹsiwaju ninu orin rẹ lati yin Ọlọrun ati lati fi han gẹgẹ bi Onidajọ gbogbo aye, Onidajọ ti ẹnikẹni ko le yẹ lọwọ wo tabi di lọwọ lati ṣe idajọ otitọ ati ododo lọna ti o ba wu u. Iwọ naa wo nkan ti wolii yi i kọ silẹ nipa Ọlọrun gẹgẹ bi onidajọ:
“Ọlọrun yoo wa lati Temani, ibi mimọ julọ lati oke Parani ogo rẹ si bo awọn ọrun, ile aye si kun fun iyin rẹ. Didan rẹ si dabi imọlẹ ooru itansan imọlẹ jade wa lati ọwọ rẹ, nibi ti wọn fi agbara rẹ pamọ si. Ajakalẹ-aarun n lọ ni iwaju rẹ; iyọnu si n tọ ẹsẹ rẹ lọ. O duro, o si mi aye; o wo, o si mu awọn orilẹ-ede wariri a si tu awọn oke nla ayeraye ka, awọn oke keekeeke ayeraye si tẹriba: ọna rẹ ayeraye ni. Mo ri agọ Kuṣani ninu ipọnju ati awọn ibugbe Midiani ninu irora. Njẹ iwọ ha n binu si awọn odo ni Ọluwa? Njẹ ibinu rẹ wa lori awọn odo ṣiṣan bi? Ibinu rẹ ha wa sori Okun ti iwọ fi n gun ẹṣin, ati kẹkẹ igbala rẹ? A ṣi ọrun rẹ silẹ patapata gẹgẹ bi ibura awọn ẹya, ani ọrọ rẹ iwọ si fi odo pin ilẹ aye. Awọn oke nla ri ọ wọn si wariri agbara ojo n ṣan an kọja lọ; ibu n ke ramuramu o si gbe iru omi soke. Oorun ati Oṣupa duro jẹẹjẹ ni ibugbe wọn, pẹlu imọlẹ ọfa rẹ ni wọn yara lọ, ati ni didan ọkọ rẹ ti n kọ mana. Ni irunu ni iwọ rin ilẹ naa ja, ni ibinu ni iwọ ti tẹ awọn orilẹ-ede rẹ. Iwọ jade lọ lati tu awọn eniyan rẹ silẹ, ati lati gba ẹni ami ororo rẹ la, iwọ ti run awọn olori kuro ninu ilẹ awọn eniyan buburu, o si bọ ihamọrẹ rẹ lati ori de ẹsẹ. Pẹlu ọkọ rẹ ki o fi gun ori rẹ nigba ti awọn jagunjagun rẹ jade lati tu wa ka, ayọ wọn si ni lati jẹ talaka run ni ikọkọ. Iwọ fi ẹṣin rẹ rin Okun ja, o si da awọn omi nla ru. Mo gbọ, ọkan mi si wariri, ete mi si gbọn si iro naa; ibajẹ si wọ inu Egungun mi lọ, ẹsẹ mi si wariri, mo duro ni idakẹ jẹẹ fun ọjọ idaamu lati de sori awọn eniyan to n dojukọ wa.” (Habakuku 3:3-16)
Ki ni gbogbo atotonu wolii yi da le lori ninu orin yi? Oun naa ni pe Onidajọ gbogbo agbaye ni Ọlọrun. Ti O ba si ṣetan lati ṣe idajọ, ko si ẹni ti o le da duro. Nitorina, daju-ṣaka ni o ye wolii yi pe awọn nikan kọ ni Ọlọrun yoo ṣe idajọ wọn; yoo tun ṣe idajọ awọn ti O n lo lati ṣe idajọ wọn naa pẹlu. Asiko wo wa ni Ọlọrun fẹ ṣe idajọ awọn wọnyi? Abakuku ko le sọ. Amọ ṣa, o ṣetan lati duro ni idakẹ jẹẹ titi ọjọ idajọ wọn yoo fi de.
Ki wa ni eyi n kọ wa? Oun naa ni pe ko ye ki a sọ ireti nu lori idajọ ododo Ọlọrun. Lotitọ, o le dabi eni pe awọn nka eniyan yoo lọ lalai jẹ iya eṣẹ wọn. Ṣugbọn ko si ika eniyan ti Ọlọrun ko ni ṣe idajọ rẹ ti ko ba ronupiwada ṣaaju asiko idajọ rẹ. Idajọ ododo Ọlọrun yoo pada wa sori gbogbo ika eniyan. Nitorina, awa ti a jẹ ti Ọlọrun ti a si n gbadura pe ki idajọ ododo rẹ fi ẹsẹ mulẹ ni ilẹ wa ati ni awujọ wa ko gbọdọ rẹwẹsi rara. Nṣe ni ki awa naa duro ni idakẹ jẹẹ titi Ọlọrun yoo fi gbe igbesẹ lati ṣe idajọ iwa ibi yowu ti o le maa lọ ni ayika wa.
Ni ipari orin wolii yi, ẹ̀wẹ̀, o fi han wa ipinnu rẹ lati tẹsiwaju lati ma yọ ninu Oluwa, bi o tilẹ jẹ wipe akoko idajọ ati idaamu ni orilẹ-ede rẹ wa. Wo nkan ti o sọ:
“Bi igi ọpọtọ ko tilẹ tanna, ti eso ko si ninu ajara; ti igi olifi ko le so, awọn oko ko si mu ounjẹ wa; ti a si ke agbo ẹran kuro ninu agbo, ti ko si si ọwọ ẹran ni ibusọ mọ, sibẹ, emi o layọ ninu Oluwa, emi yoo si maa yọ ninu Ọlọrun igbala mi. Oluwa Olodumare ni agbara mi, oun yoo si ṣe ẹsẹ mi bi ẹsẹ abo agbọnrin, yoo si mu mi rin lori ibi giga. Si olori akọrin lori ohun elo orin olokun mi.” (Abakuku 3:17-19)
Njẹ o ri bayi? A ko gbọdọ jẹ ki aini, rogbodiyan tabi ohunkohun di yiyọ wa ninu Oluwa lọwọ. Eyi ja si pe ko ki i ṣe igba ti nkan ba rọgbọ nikan ni o yẹ ki a ma layọ ninu Oluwa. Boya nkan rọgbọ tabi ko rọgbọ, nṣe ni o yẹ ki a ma yọ ninu rẹ. Ọpọ ni o ma n fajuro ti nkan ko ba ti lọ deede fun wọn, ti wọn yoo si ma ṣe aroye. Ṣugbọn aṣẹ Ọlọrun fun wa ni pe ki a ma a yọ ninu Oluwa nigba gbogbo (Filipi 4:4). Ẹni ti ko ba si pa aṣẹ yi mọ ko le ni iriri iyanu Ọlọrun ti yoo jẹ ki ayọ rẹ kun akunwọsilẹ.
Bi Abakuku ti ṣe jẹ ki o ye wa, idi ti o ṣe pinnu lati ma a yọ ninu Oluwa, bi o tilẹ jẹ wipe nkan ko rọgbọ fun, ni pe o ri Oluwa gẹgẹ bi agbara rẹ. Eyi ja si wipe ko ni ṣe alaini anito agbara ti o nilo lati bori asiko idaamu ti o ba ara rẹ nitori ẹṣẹ orilẹ-ede rẹ. Ti awa naa ba si ri Ọlọrun gẹgẹ bi agbara wa, gẹgẹ bi aabo wa ati gẹgẹ bi Olutunu wa, ti a si n yọ ninu rẹ, yala nkan rọgbọ fun wa o tabi ko rọgbọ fun wa, o di dandan ki a ni iriri agbara rẹ lati gbe wa ga, lati daabo bo wa ati lati jẹ ki a bori gbogbo iṣoro aye wa.
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Alagbara, onidajọ ododo ati alaanu ni Oluwa Ọlọrun wa. Nitorina, a le fi igbekẹle wa sinu rẹ pe yoo pada ṣe idajọ ohun gbogbo ti o n jẹ iwa ibi ti awọn eniyan le ma a wu. Amọ ni asiko ti o ba n ṣe idajọ yi, o ṣeeṣe ki awọn eniyan rẹ naa fi ara gba nibẹ. Nitorina, bi a ti ṣe n ke pe Ọlọrun fun idajọ ododo lori ilẹ wa naa ni o yẹ ki a ma sọ fun pe ki O ranti aanu rẹ ti O ba n ṣe idajọ. Aijẹbẹ, awọn alaiṣẹ naa le ba idajọ lọ. Ti a ba si wa ba ara wa ni asiko idajọ tabi idaamu, a ko gbọdọ rẹwẹsi tabi ma a ṣe aroye. Dipo eyi, nṣe ni ki a ma a yọ ninu Oluwa Ọlọrun wa. Ki a wa ma gbagbe pe yiyọ ninu Oluwa yatọ si yiyọ ninu iṣoro wa. Abakuku kọ yọ ninu iṣoro ati idaamu ti o n ba finra ninu orilẹ-ede rẹ. Dipo eyi, inu Oluwa ni o ti n yọ. Ti awa naa ba si n ṣe bẹẹ gẹgẹ, o di dandan ki a ri ogo Ọlọrun.
ÌBÉÈRÈ
– Ki ni iyatọ ti o wa ninu ki a ma yọ ninu Oluwa ati ki a ma ṣogo lori idaamu tabi iṣoro wa?
– Mẹnuba awọn anfaani ti o wa ninu ki a ma a yọ.
Lati ọwọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2025 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)
ÀKỌ́RÍ: ÌTÀKÙRỌSỌ PẸ̀LÚ ỌLỌ́RUN | ÀYỌKÀ: ÁBÁKÚKU 1:1-17 | ỌJỌ́RÚ 19, ẸRẸ́NÀ 2025
ÀKỌ́SÓRÍ: “Emi yoo duro lori ibusọ mi lati maa woye. Emi yoo si gbe ara mi ka ori alore. Emi yoo si sọ lati gbọ ohun ti yoo sọ fun mi ati esi ti emi yoo fun ẹsun yii nigba to ba n ba mi wi.” (Ábákúkù 2:1)
Ọ̀RỌ̀ ÌSÀÁJÚ
Iwe wolii Abakuku jẹ ọkan lara awọn iwe awọn wolii ti Ọlọrun lo lati ba awọn eniyan Isiraẹli ati Juda sọrọ ni awọn asiko ti a n ko wọn lọ si igbekun. Bi o tilẹ wa jẹ wipe a ko mẹnuba irufẹ eniyan ti Abakuku jẹ, ibi ti o ti ṣẹ wa ati bi o ti ṣe gba ipe rẹ gẹgẹ bi wolii Ọlọrun, akọsile inu iwe rẹ jẹ ki o ye wa pe asiko ti awọn ara Babiloni bẹrẹ si ni kọlu awọn orilẹ-ede ti o wa ni ayika wọn lati jẹ gaba le wọn lori ni wolii yi ṣe iṣẹ iranṣẹ rẹ. Iyatọ ti o kan wa lara awọn akọsilẹ inu iwe rẹ si ti awọn wolii yoku ni pe o kun fun itakurọsọ laarin oun ati Ọlọrun. Wolii yii bere awọn nkankan ti o ruju nipa idajọ Ọlọrun lọwọ rẹ. Eyi si jẹ koko nkan ti o bi isọtẹlẹ rẹ. Njẹ a wa le ri ẹkọ kankan kọ lara awọn nkan ti o kọ silẹ, bi o tilẹ jẹ wipe ko pọ lọ titi? Bẹẹ ni. Awọn ẹkọ wọnyi si ni a fẹ gbe yẹwo bi a ti ṣe n gbe iwe naa yẹwo. Njẹ ki Ẹmi Ọlọrun fun wa ni oye ti o peye lori rẹ, ni orukọ Jesu Oluwa wa. Amin.
ÌTÀKÙRỌSỌ PẸ̀LÚ ỌLỌ́RUN
Nkan akọkọ ti a ri ninu iwe Abakuku ni pe o fi ẹsun kan Ọlọrun lori ilọra rẹ lati ṣe idajọ iwa ika. Iwọ naa wo nkan ti osọ:
“Iran ti wolii Abakuku ri. Oluwa, emi yoo ti ke pẹ to fun iranlọwọ, Ṣugbọn ti iwọ ko ni feti si mi? Tabi kigbe si ọ ni ti, “Iwa ipa!” ṣugbọn ti iwọ ko si gbala? Eeṣe ti iwọ fi mu mi ri aiṣedeede, eeṣe ti iwọ si faaye gba iwa ika? Iparun ati iwa ipa wa ni iwaju mi; ija n bẹ, ikọlu si wa pẹlu. Nitori naa, ofin di ohun aikasi, idajọ ododo ko si bori. Awọn ẹni buburu yi awọn olododo ka, Nitori naa ni idajọ ododo ṣe yi pada.” (Ábákúkù 1:1-4)
Njẹ ko ti si awọn asiko ti o dabi ẹni wipe awa naa n ke pe Ọlọrun, ti ko si gbọ, awọn asiko ti o da bi ẹni pe Ọlọrun ko kiyesi iwa ika ti o n gbilẹ ni awujọ wa? Bẹẹ gẹgẹ ni o ti ṣe ri loju Abakuku ni asiko ti a n sọ yi. Ko ye ọkunrin yi idi ti iwa ika ṣe n gbilẹ ni awujọ rẹ, ti o si n kigbe pe Ọlọrun lari ṣe nkan nipa rẹ, ti ko si dabi ẹni pe O n gbọ debi wipe yoo tilẹ dahun. O wa n jẹ ki o ye Ọlọrun wipe aikọbiara si iwa ika ti o n lọ ni orilẹ-ede rẹ ni o jẹ ki ofin di ohun aikasi laarin awọn eniyan, ti ododo ko si ri aye rara.
Ṣe Ọlọrun wa da lohun tabi ko da lohun? Ọlọrun kuku da a lohun. Wo idahun ti Ọlọrun fun un:
“Ẹ wo inu awọn alaikọla, ki ẹ si woye, ki Iyalẹnu ki o si ṣe yin gidigidi. Nitori ti emi yoo ṣe ohun kan ni owurọ ọjọ ọ yin ti ẹyin ki yoo si gbagbọ bi o tilẹ jẹ pe a sọ fun un yin. Nitori pe, emi yoo gbe awọn ara Babiloni dide, awọn alailaaanu ati oninu fufu eniyan ti o rin gbogbo ilẹ aye ja lati fi agbara gba awọn ibugbe ti ki i ṣe ti wọn. Wọn jẹ eniyan ti a bẹru, ti a si paya, idajọ wọn, ati ọlanla wọn, yoo maa ti inu wọn jade. Eṣin wọn yara ju ẹkun lọ, wọn si gbọna ju ikoko aṣalẹ lọ. Awọn ẹlẹṣin wọn yoo si tan ara wọn ka; awọn yoo si wa lati ọna jinjin rere, wọn yoo si fo bi ẹyẹ igun ti n wa lati jẹrun. Gbogbo wọn si wa fun iwa ipa, iwo oju wọn yoo si wa siwaju; wọn si ko igbekun jọ bi i yanrin. Wọn o si maa fi awọn ọba ṣẹṣin, wọn o si tun kẹgan awọn alade. Wọn yoo si fi gbogbo ilu odi alagbara ni rẹrin; Nitori pe, wọn yoo ko erupẹ jọ, wọn yoo si gba a. Nigba naa ni inu rẹ yoo yipada, yoo si rekọja, yoo siṣẹ ni kika agbara rẹ yii si iṣẹ oriṣa rẹ.” (Ábákúkù 1:5-11)
Bawo ni idahun ti Ọlọrun fun Abakuku ninu awọn ẹsẹ bibeli yi ṣe jọ mọ ibere ti o n bere lọwọ rẹ? Oun fẹ mọ idi ti Ọlọrun ṣe fọwọ lẹran, ti ko si ṣe idajọ awọn iwa ika ati iwa ibi ti o n lọ ni orilẹ-ede rẹ. Ṣugbọn idahun ti Ọlọrun fun tun wa ya a lẹnu kọja nkan ti o lero. Ọlọrun n jẹ ki o ye wipe Oun ko fọwọ lẹran rara. Eyi tunmọ si pe Oun yoo ṣe idajọ iwa ika ati iwa aiṣododo ti o n lọ lọwọlọwọ ni awujọ rẹ. Amọ ọna ti Oun yoo gba ṣe idajọ awọn nkan wọnyi ni o yatọ — o jẹ ọna ti o kọja nkan ti wọn le gbagbọ, ti wọn ba tilẹ gbọ.
Ọna wo wa ni Ọlọrun fẹ gba ṣe idajọ iwa ika ti o n lọ ni orilẹ-ede Juda ni asiko yi? Oun naa ni nipa mimu awọn ara Babilonia wa lati fiya jẹ wọn. Bi mo ti ṣe sọ siwaju, ni asiko yi, orilẹ-ede Babiloni ti n gbe igbesẹ lati fi ara rẹ han gẹgẹ bi orilẹ-ede ti o lagbara ju ni agbaye. Wọn ti n lọ lati iṣẹgun de iṣẹgun. Wọn si ti fi ọpọ awọn ọba alade ṣe ẹlẹya. Awọn kan naa yi wa ni Ọlọrun fẹ lo lati ṣe idajọ awọn eniyan rẹ? Ki ni idi?
Akọkọ, bibeli sọ eyi fun wa: “Ṣugbọn ti awa ba wadi ara wa, a ki yoo da wa lẹjọ.” (1Kọ́ríntì 11:31) Nkan ti Ọlọrun fẹ ki o ye wa nibi yi ni wipe, ti a ba n ṣe idajọ ara wa ni ibamu pẹlu otitọ, Oun ko ni nilo lati da wa lẹjọ. O ja si pe, ti awọn eniyan ba n ṣe nkan ti ko dara, yala ninu ijọ Ọlọrun ni, ninu ile wa ni tabi ni awujọ wa, ti a si n ri daju pe a n ṣe idajọ wọn ni bi o ti ṣe tọ ati yẹ, Ọlọrun ko ni nilo lati ṣe idajọ wa mọ lori ọrọ kan naa, iyẹn ninu aye yi.
Amọ ti a ba kọ lati ṣe idajọ ara wa tabi idajọ awọn ti o wa ni abẹ iṣakoso wa ni asiko, Ọlọrun, ti o jẹ onidajọ ododo, di dandan ki o gbe igbesẹ lati ṣe idajọ wa lọna ti o tọ ati ti o yẹ loju rẹ. A si ri apẹrẹ eyi lati ara Alufa Eli ati awọn ọmọ rẹ. Ọlọrun jẹ ki o ye alufa yi pe o wa ni ipo ẹni ti o yẹ ki o wadi awọn ọmọ rẹ, ki o si tun ṣe idajọ wọn lọna ti o yẹ fun gbogbo awọn iwa ibi wọn, ti ko si ṣe bẹẹ, Nitorina, Oun yoo ni lati ṣe idajọ idile rẹ. Bẹẹ gẹgẹ ni o si ṣe ri fun idile alufa yi. (Wo: 1Sámúẹ́lì 2-4)
Ni afikun, a jẹ ki eyi ye wa ninu lẹta Pọọlu si awọn ara Roomu idi ti Ọlọrun fi n fi awọn eniyan si ipo adari:
“Nitori adajọ ko wa lati dẹru ba awọn ẹni ti n ṣe rere. Ṣugbọn awọn to n ṣe buburu yoo maa bẹru rẹ nigba gbogbo. Nitori idi eyi, pa ofin mọ iwọ ko si ni gbe ninu ibẹru. Nitori iranṣẹ Ọlọrun ni lati ṣe ọ ni rere. Ṣugbọn bi o ba ṣe nkan buburu, maa bẹru, nitori ko ru ida naa lasan. Nitori iranṣẹ Ọlọrun ni i ṣe, iranṣẹ ibinu si ara awọn ẹni ti n ṣe buburu.” (Róòmù 13:3-4)
Njẹ o ri bayi? Ara idi ti Ọlọrun fi n fi awọn eniyan si ipo iṣedari ni ki wọn ba a le ma ṣe idajọ iwa ibi. Ti a ba wa ri awujọ ninu eyi ti iwa ibi ti gbilẹ, ti ododo ṣi kọsẹ tabi ṣubu, a jẹ wipe awọn ti o jẹ adari nibẹ ti kọ lati ma ṣe ifẹ Ọlọrun niyẹn. Ti o ba wa ya, Ọlọrun yoo bẹrẹ si ni gbe igbesẹ lati ṣe idajọ iwa ika ti o wa ni awujọ naa, eyi ti awọn adari wọn ti kọ lati ṣe. Ọna ti yoo gba ṣe eyi wa ni a le ma le e sọ. O le lo ogun. O le lo iyan. O le lo ajakalẹ-arun. O si le lo ikọlu awọn ẹranko buburu. Ṣugbọn o di dandan ki O ṣe idajọ bopẹ-boya, ti awọn ti a fi ṣe adari ba kọ lati ma ṣe e ni ọna ti o peye. (Wo: Ìsíkíẹ̀lì 14:12-21)
Nkan ti a n gbiyanju lati sọ ni wipe niwọn igba ti awọn adari orilẹ-ede Juda ti kọ lati jẹ ki idajọ ododo mulẹ ni awujọ wọn, o di dandan ki Ọlọrun gbe igbesẹ lati ṣe idajọ gbogbo orilẹ-ede naa. Awọn ti O si ti pinu lati lo ni awọn ara Babiloni. Ki wa lo de ti O fi jẹ wipe awọn ara Babiloni ni Ọlọrun fẹ lo lati jẹ awọn eniyan rẹ niya? Ṣe awọn wọnyi san ju awọn ara Juda lọ ni? Rara o! Ko ki i ṣe nitoripe awọn ara Babiloni san ni iwa rere ju awọn ara Juda lọ ni Ọlọrun ṣe fẹ lo wọn lati pọn awọn ara Juda loju. Wọn ko san ju wọn lọ rara. Abọriṣa pọnbele tilẹ ni wọn jẹ. Amọ ti a ba ti n sọrọ nipa idajọ Ọlọrun, ko si ẹni ti ko le lo gẹgẹ bi pasan idajọ rẹ, yala iwa ẹni naa dara tabi ko dara. Ki a tilẹ sọ otitọ, ọpọ igba ni o jẹ wipe awọn ti iwa wọn ko dara, awọn ti wọn kun fun ika ni gbogbo ọna, ni Ọlọrun ma n ṣaba lo lati ṣe pasan idajọ fun awọn alaigbọran eniyan.
Nitorina, ti a ba n dẹṣẹ, ti a si n kọ eti ikun si aṣẹ Ọlọrun, ẹnikẹni ni O le lo lati jẹ wa niya. Ti oye ko ba si ye wa, a le bẹrẹ si ni ba a binu tabi ba a ja. Bi a ti ṣe ri siwaju si ninu iwe Abakuku, orin ikinni ti a n wo yi, ọrọ yi ko ye wolii naa rara. Bawo ni Ọlọrun ṣe le lo awọn ti ẹṣẹ wọn pọ ju ti awọn ara Juda lọ lati pọn wọn loju? Loju tirẹ, awọn ti o ba jẹ olododo ju wọn lọ ni o yẹ ki Ọlọrun lo lati jẹ wọn niya, ti o ba tilẹ jẹ wipe o di dandan fun lati jẹ wọn niya. Idi si ni yi ti o fi tẹsiwaju lati sọ awọn nkan wọnyi fun Ọlọrun:
“Oluwa, njẹ lati ayeraye kọ ni iwọ ti wa. Oluwa Ọlọrun mi. Ẹni mimọ mi, awa ki yoo ku Oluwa, iwọ ti yan wọn fun idajọ; Ọlọrun alagbara, iwọ ti fi ẹṣẹ wọn mulẹ fun ibawi. Oju rẹ mọ tonitoni lati wo ibi; iwọ ko le gba iwa ika. Nitori ki ni iwọ ṣe gba awọn alarekereke laaaye? Nitori ki ni iwọ ṣe dakẹ nigba ti ẹni buburu n pa ẹni ti i ṣe olododo ju wọn lọ run? Iwọ si ti sọ eniyan di bi ẹja inu okun, bi ohun ti n rako ti wọn ko ni alakooso. Awọn eniyan buburu fi awọn wọn gbe wọn soke, o si ko wọn jọ ninu àwọ̀n nla rẹ; nitori naa, o dunnu, o si yọ pẹlu. Nitori naa, o ru ẹbọ si awọn rẹ, o si n sun turari fun awọn nla rẹ nitori pẹlu awọn rẹ ni o fi n gbe ni igbadun ti o si n gbadun pẹlu ounjẹ ti o ba wu u. Njẹ wọn yoo ha maa pa awọn wọn mọ ni ofifo bi, ti wọn yoo si pa orilẹ-ede run laisi aanu?” (Ábákúkù 1:12-17)
Ki ni a ri nibiyi? A ri wipe Abakuku tẹsiwaju ninu itakurọsọ rẹ pẹlu Ọlọrun. O n fẹ mọ idi ti Ọlọrun ṣe pinnu lati lo orilẹ-ede abọriṣa bi ti awọn ara Babiloni lati ṣe idajọ awọn eniyan rẹ, lati ko wọn bi awọn apẹja ti n fi awọn wọn ko ẹja lodo. Ṣe Ọlọrun wa da lohun tabi ko da lohun? Ti O ba si da lohun, irufẹ idahun wo ni O fun un? Eyi ti a o ri ninu ori ikeji iwe yi i.
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Amọ ṣa o, a ko gbọdọ gbagbe pe koko ori akọkọ iwe naa ni pe Ọlọrun ko ni foju fo iwa ika ni ibibiki, ti awọn ti o wa ni ipo lati ṣe idajọ rẹ ba kọ lati ṣe e. Ọna ti o ba si wu u ni O le lo lati ṣe idajọ iwa ika. Nitorina, ti a ba wa ni ipo ẹni ti o le dẹkun iwa ika tabi iwa ibajẹ, yoo dara ki a ri daju pe a n lo ipo wa lati ṣe bẹẹ gẹgẹ. Aijẹbẹ, nigba ti o ba to asiko, Ọlọrun yoo gbe igbesẹ lati ṣe idajọ iwa ibi yowu ti a ba n foju rena. O si wa ṣeeṣe ki awa naa fi ara gba nibẹ.
ÌBÉÈRÈ
– Darukọ awọn ọna ti o lero wipe Ọlọrun n lo lati ṣe idajọ iwa ika ni orilẹ-ede wa.
– Ki ni o ṣe pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi?
Lati ọwọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2025 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)
ÀKỌ́RÍ: SÁKÉÙ | ÀYỌKÀ: LÚÙKÙ 19:1-10 | ỌJỌ́RÚ 19, ÈRÈLÉ 2025
ÀKỌ́SÓRÍ: “Nitori Ọmọ Eniyan de lati wa awọn ti o nu kiri, ati lati gba wọn la.” (Lúùkù 19:10)
Ọ̀RỌ̀ ÌSÀÁJÚ
Lara awọn itan inu bibeli ti o n tọka si bi a ti ṣe le jẹ igbadun Ọlọrun ati ipese igbala rẹ ni itan ọkunrin kan ti a n pe ni Sakeu. Tani Sakeu? Ẹkọ wo ni a le ti ara rẹ kọ? Ẹkọ wo si tun a le ti ara iṣẹ-iranṣẹ Jesu si ọkunrin yi kọ? Awọn nkan ti a fẹ gbeyẹwo ninu akọsilẹ bibeli lori Sakeu ni eyi. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun fun wa ni oye ti o peye ati ti o yanju lori ẹkọ naa, ki O si tun fun wa ni okun lati ṣe amulo awọn nkan ti a o kọ. Amin.
TANI SÁKÉÙ?
Ta wa ni Sakeu? Diẹ lara nkan ti a kọ silẹ sinu bibeli nipa rẹ ni iwọnyi:
“Jesu si wọ Jẹriko lọ, o si n kọja laarin rẹ. Si kiyesi i, ọkunrin kan wa ti a n pe ni Sakeu, o si jẹ olori agbowo ode kan, o si jẹ ọlọrọ. O si n fẹ lati ri ẹni ti Jesu jẹ: ko si le ri i, nitori ọpọ eniyan, ati nitori ti oun jẹ eniyan kukuru.” (Lùùkù 19:1-2)
“Jesu si wi fun un pe, “Loni ni igbala wọ ile yii, niwọn bi oun pẹlu ti jẹ ọmọ Aburahamu.”” (Lúùkù 19:9)
Akọkọ, bi a ti ṣe ri ninu awọn ẹṣẹ bibeli yi, Sakeu jẹ iru ọmọ Aburahamu. A ko mọ ẹya Isiraẹli ti o jẹ. Ṣugbọn a ṣa ri mọ wipe iru ọmọ Aburahamu ni oun i ṣe. Nitorina, o jẹ ọkan lara awọn ti awọn ibukun ti Ọlọrun ṣe ileri fun Aburahamu, paapaa julọ ibukun igbala ati isọdọmọ, wa fun. Ara idi ti Jesu ko fi lọra tabi tiju lati wọ ile rẹ ni eyi.
Ekeji, Sakeu jẹ ọkan lara awọn olori agbowo ode. Awọn wo wa ni awọn agbowo ode? Awọn agbowo ode ni ilẹ Juda ni asiko yi ni awọn ti o n ba ijọba Roomu ṣiṣẹ lati gba oniruuru owo ori lọwọ awọn eniyan. A tilẹ ri ka ninu bibeli pe agbowo ode naa ni Matiu (Lefi), ẹni ti o jẹ ọkan lara awọn apọsiteli Jesu (Mátíù 9:9-10; Lúùkù 5:27-30). Amọ, bi a tun ṣe ri ninu bibeli, awọn eniyan ko fi taratara fẹran awọn ti o n ṣiṣẹ yi. Idi si ni pe iwa-ibajẹ pọ lọwọ wọn.
Fun apẹrẹ, ni asiko ti Johanu onitẹbọmi n waasu, awọn agbowo ode naa wa si ọdọ rẹ lati gbọ ọrọ Ọlọrun lẹnu rẹ. Wo nkan ti a kọ silẹ pe o wi fun wọn:
“Awọn agbowo ode si tọ ọ wa lati itẹbọmi lọdọ rẹ, wọn si bi i pe, “Olukọ, ki ni awa o ha ṣe?” O si wi fun wọn pe, “ Ẹ ma ṣe fi agbara gba ju bu a ti ran yin lọ.” (Lúùkù 3:12-13)
Ṣe iwọ naa ri ara idi ti awọn eniyan ko fi gba ti awọn agbowo ode lọ titi bayẹn? Wọn ma n fi agbara ati ọna eru gba owo lọwọ awọn eniyan ju nkan ti o yẹ ki wọn gba lọ. Ọpọ ninu wọn lo si ti tipasẹ eyi di ọlọrọ. Sakeu funrarẹ gan fi han ninu ọrọ rẹ si Jesu pe iṣẹ ọwọ oun, gẹgẹ bi agbowo ode, lati di ọlọrọ ko mọ. Wo nkan ti o sọ:
“Woo, Oluwa, aabọ ohun ini mi ni mo fifun talaka; bi mo ba si fi eke gba ohun kan lọwọ ẹnikẹni, emi san an pada ni ilọpo mẹrin!” (Lúùkù 19:8)
Ọkunrin yi sọ wipe ti oun ba fi eke gba ohunkohun lọwọ ẹnikẹni, o n ṣetan lati da pada ni ilọpo mẹrin. Eyi jasi pe o mọ lọkan rẹ wipe awọn kan wa ti o n ti yanjẹ sẹyin, ti oun si ti ti ara wọn di ọlọrọ lọna eru. Idi niyi ti o ṣe mura lati ṣe atunṣe pẹlu irufẹ awọn wọnyi.
Ni kukuru, iṣẹ agbowo ode ni asiko yi ko ki i ṣe iṣẹ ti awọn eniyan fi ma n tọrọ fun awọn ọmọ wọn. Dipo eyi, iṣẹ ti o kun fun ọpọ onibajẹ eniyan ati ẹlẹṣẹ ni. Idi niyi ti o fi jẹ wipe gbogbo ibi ti a ba ti darukọ awọn agbowo ode ninu bibeli ni a ti n fẹrẹ ka wọn si ẹlẹṣẹ. (Wo: Mátìù 9:10-11; Lúùkù 18:9-14; Lúùkù 19:7)
Ẹkẹta, a ri wipe ọlọrọ ni Sakeu. O si ni ọrọ de ibi ti o lapẹrẹ. Idi niyi ti o fi sọ fun Jesu pe o n ṣetan lati fi idasimeji nkan ini rẹ fun awọn talaka. Yatọ si eyi, o tun ṣeleri lati fun ẹnikẹni ti o ba ti yan jẹ ri ni ilọpo merin ohun yowu ti o fi ọna eru gba lọwọ rẹ. Nibo ni yoo ti ri ilọpo mẹrin nkan ti o ti fi eru gba lọwọ awọn eniyan da pada? O ni lati jẹ wipe o ti ni ọpọlọpọ ọrọ ni asiko yi niyen.
Ẹkẹrin, a tun ri wipe eniyan kukuru ni Sakeu. Eyi si n jẹ ki o ye wa pe ki eniyan kuru ko tunmọ si pe ko ni oye tabi pe ko le di ọlọrọ tabi ki o di ẹni giga tabi eniyan pataki laye ati lawujọ yowu ti o ba wa. Bẹẹ ṣi ni ki eniyan ga gogoro ko tunmọ si pe ọpọlọ rẹ ji pepe tabi pe ko ni ṣe ẹru ẹgbẹ. Iha ti ẹnikọọkan wa ba kọ si awọn anfaani ti Ọlọrun ba fun wa laye ni yoo sọ bi a o ti ṣe ga to tabi di ẹni pataki si ni aye yi.
Ẹ̀KỌ́ LÁTI ARA SÁKÉÙ
Wayi o, ki wa ni awọn ẹkọ ti a le ri kọ lara Sakeu ati ipade rẹ pẹlu Jesu? Ara awọn ẹkọ ti a le ri kọ ni iwọnyi:
Ìpòngbẹ fún Ọlọ́run: Pẹlu gbogbo awọn nkan ti a sọ nipa Sakeu, pe o jẹ agbowo ode ati ẹlẹṣẹ, a si tun ri wipe o n pongbẹ ninu ọkan rẹ fun Ọlọrun ati fun igbala. A sọ ninu akọsilẹ itan rẹ pe, “O si n fẹ lati ri ẹni ti Jesu jẹ…” (Lúùkù 19:3) Ki ni idi ti o se n fẹ ri Jesu? Idi ni pe bi o tilẹ jẹ ẹlẹṣẹ, igbala ọkan rẹ jẹ ẹ logun. Bi o tilẹ si tun jẹ wipe ọlọrọ ni, ẹni ti o ni anfaani lati jẹ igbadun awọn nkan ti aye yi lọpọlọpọ, ibi ti yoo ti lo ayeraye rẹ jẹ ẹ ni ogun. Idi niyi ti oun naa ṣe fẹ sumọ Ọlọrun si. Nitorina, pe eniyan jẹ olowo tabi ẹlẹṣẹ ko tunmọ si pe ko si aye rara ninu ọkan rẹ fun Ọlọrun. Pe eniyan si jẹ talaka tabi ẹni ti o n ṣe fefe ko tunmọ si pe o ni aye fun Ọlọrun ninu ọkan rẹ. Ẹnikẹni ti ko ba pongbẹ fun Ọlọrun, ko le di ẹni igbala. Nitoripe ipongbẹ fun Ọlọrun ni o ma n ṣiṣẹ fun igbala. Boya a wa ni ọrọ tabi a ko ni, boya a mọ wa ṣi ẹlẹṣẹ paraku tabi si ẹni ire, niwọn igba ti ọkan wa ba ti n pongbẹ fun Ọlọrun, o di dandan ki O fi igbala rẹ sọwọ si wa. Idi si niyi ti a o fi ri awọn ọlọrọ bi Aburahamu ninu ijọba Ọlọrun, ti a o si ri ọpọ talaka pẹlu ni ọrun apadi. (Wo: Lúùkù 16:19-31; Ìṣe Àpọ́sítélì 10)
Títọ ọ̀nà òtítọ́: Ẹkọ miran ti a tun ri kọ lati ara Sakeu ni pe o wa igbala rẹ si ibi ti o tọ. O wa igbala rẹ si ọdọ Jesu. Ranti pe a sọ eyi fun wa nipa rẹ: “O si n fẹ lati ri ẹni ti Jesu jẹ…” (Lúùkù 19:3) Ki ni idi ti o ṣe jẹ wipe Jesu ni o n fẹ lati ri? Ki ni idi ti ko ṣe gba ọdọ awọn farisi tabi sadusi ti o wa ni ilẹ naa lọ? Idi ni pe ninu ọkan rẹ o mọ wipe awọn wọnyi ko le ran oun lọwọ ati wipe ẹnikan ṣoṣo ti o le e ran lọwọ ni Jesu. Bawo ni o ṣe mọ? O ni lati jẹ wipe o ti gburo Jesu, igbe aye ododo rẹ, iwaasu rẹ, iṣẹ iwosan ati iṣẹ imunilarada rẹ daradara. Jesu funrarẹ si ti wa sọ wipe: “Ẹkọ mi ki i ṣe temi, bi ko ṣe ti ẹni ti o ran mi. Bi ẹnikẹni ba fẹẹ lati ṣe ifẹ rẹ yoo mọ ni ti ẹkọ naa, bii ba ṣe ti Ọlọrun, tabi bi emi ba sọ ti ara mi.” (Jòhánù 7:16-17) Njẹ o ri bayẹn? Ni kete ti ẹnikẹni ti o ba fẹ ṣe ifẹ Ọlọrun ba gbọ ọrọ ifẹ ati igbala Jesu ni yoo ti mọ wipe Ọlọrun funrarẹ ni O n ba oun sọrọ. Ṣugbọn bi ẹni ti ko ni lọkan lati ṣe ifẹ Ọlọrun ba tilẹ gbọ ohùn tabi ẹkọ Jesu, ko ni kọbiara si rara. Iru wọn ni wọn ma n wa igbala lọ si ibi ti ko ti si.
Àìjáfira: Ni ọjọ ti Sakeu gbọ wipe Jesu n la ilu oun, iyẹn Jeriko, kọja, ko ṣe meni tabi meji ti o fi gbera lati fi oju gaani rẹ. Eyi tunmọ si pe o pa ohun yowu ti o n ṣe ni asiko naa ti lati ri Jesu. Ki ni idi? Idi ni pe ipongbẹ rẹ fun Ọlọrun ati igbala ọkan rẹ pọ gidigidi. Eyi jẹ ki o ri rírí Jesu bi nkan ti o ṣe pataki julọ si ni asiko naa. Yatọ si eyi, o mọ lọkan rẹ pe o ṣeeṣe ki irufẹ anfaani ti o yọju ni ọjọ yi ma tun lailai yọju mọ. Nitorina, ti o ba lọ jafara ni, o ṣeeṣe ki o padanu riri Jesu ati igbala ti o sọrọ mọ. Eyi si n kọ wa pe awọn anfaani kan wa lati mọ Ọlọrun si, lati di ẹni igbala tabi lati ri awọn nkankan gba lọwọ Ọlọrun ti o le e ma tọ wa wa ju ẹkan lọ. Ti a ba wa jafara, ti a ko ri anfaani bi nkan ti o ṣe pataki julọ fun wa lati ṣe amulo ni asiko naa, o ṣeeṣe ki o bọ mọ wa lọwọ titi lailai.
Àìbìkítà fún ìdènà: Bi a tun ṣe wa ri ninu akọsilẹ bibeli nipa Sakeu, o jẹ ẹnikan ti ko bikita fun idena rara. O ṣi ṣeeṣe ki eyi gan wa lara awọn idi ti o ṣe di ọlọrọ. Wo nkan ti a sọ nipa igbesẹ ti o gbe lati ri Jesu: “O si n fẹ lati ri ẹni ti Jesu jẹ: ko si le ri i, nitori ọpọ eniyan, ati nitori ti oun jẹ eniyan kukuru. O si sure siwaju, o gun ori igi sikamore kan, ki o ba le ri i: nitori ti yoo kọja lọ niha ibẹ.” (Lúùkù 19:3-4) Idena pataki melo ni Sakeu koju ni ọjọ ti o fẹ ri Jesu fun igbala ọkan rẹ? Meji ni wọn! Akọkọ, awọn eniyan ti o n tẹle Jesu pọ jọjọ ni ọjọ ti a n wi yi. Bẹẹ si ni o ṣe ma n ṣaba ri ti Jesu ba wa ni ibikan – awọn eniyan ma n pọ lọdọ rẹ. Ẹni ti o ba wa kọbiara si eyi ṣeeṣe ki o ma le lailai ri Jesu tabi sunmọ ọn. Idena keji ni pe Sakeu funrarẹ jẹ eniyan kukuru. Nitorina, bi o tilẹ naga tabi garun, ipo ti o wa yi ko le jẹ ki o ri i. Idi si ni yi ti o fi gun igi lati le e ri. Ka wa ma gbagbe pe ọrọ ọlọrọ ni a n sọ yi o. Sibẹsibẹ, ko jẹ ki ọrọ rẹ tabi ipo rẹ lawujọ di i lọwọ lati se ohun ti o tọ lati ri Jesu. A wa ri ọpọ loni to jẹ wipe awọn nkan ti ko nitunmọ ni ko jẹ ki wọn mu Ọlọrun ni pataki tabi ki wọn ti di ẹni atunbi. Ki ni yoo jẹ awawi wọn ni ọjọ idajọ nibi ti Sakeu ba ti n sọrọ? Yatọ si awọn nkan wọny, Sakeu ko ma sa fun Jesu nitori ẹṣẹ rẹ ẹ. Ko wo wipe ẹṣe oun ti pọ ju fun Jesu lati mojuto. Dipo eyi, nṣe ni o ṣe awari rẹ. Ọpọ ni o n sa fun Ọlọrun loni nitori ẹṣẹ wọn. Ṣugbọn tani Ọlọrun ko ba gbala bikoṣe ẹlẹṣẹ? Ti o ba le gba ara rẹ lọwọ ẹṣẹ rẹ ni, o ko ni nilo Ọlọrun. Nitorina, bi o ti wu ki ẹṣẹ rẹ pọ to, nṣe ni ki o ko tọ Ọlọrun wa. Yoo si gba ọ bi o ti ri. Yoo si tun fi igbala fun ọkan rẹ.
Ayọ̀ ìgbàlà: Nkan miran ti a tun kọ lati ara Sakeu ni pataki ki a ma yọ ayọ igbala. Wo nkan ti a sọ nipa rẹ: “Nigba ti Jesu si de ibẹ, o gbe oju soke, o si ri i, o si wi fun un pẹ, “Sakeu! Yara, ki o si sọkalẹ, nitori pe emi yoo wọ ile rẹ loni.” O si yara, o sọkalẹ, o si fi ayọ gba a.” (Lúùkù 19:5-6) Ki ni Sakeu fi gba Jesu? Ayọ ni o fi gba a. Eyi jasi pe igbala otitọ ni o ri gba lọjọ ti a n wi yi. O wa ṣeni laanu loni pe ọpọ ti o n pe ara wọn ni Kirisitiẹni, ọpọ ti o n sọ wipe ọmọ Ọlọrun ni awọn, ni ayọ ko kun ọkan wọn ninu ibaṣepọ wọn pẹlu rẹ. Wọn ko layọ lati sin in. Wọn ko layọ lati gbọ ọrọ rẹ tabi lati ka ọrọ rẹ. Wọn ko si layọ lati gbadura tabi kọrin iyin. Eyi si n fihan wa pe igbala wọn mu ifura lọwọ. Ti o ba ti di ẹni igbala nitootọ, o di dandan ki ayọ igbala, ayọ ẹmi Ọlọrun, kun ọkan rẹ. (Wo: Ìṣe Àpọ́sítélì 16:33-34; Róòmù 14:17; 1Pétérù 1:8-9)
Ìgbésẹ̀ ìrònúpìwàdà: Yatọ si awọn ẹkọ ti a ti mẹnuba siwaju ti a le ri kọ lara Sakeu, a tun ri kọ lara rẹ pe o ṣe pataki ki a gbe igbesẹ ironupiwada ti a ba ti di ẹni igbala nitootọ. Ọtọ ni ki Ọlọrun dariji eniyan; ọtọ si tun ni ki ẹni naa ronupiwada. Ọpọ lo n fi ojoojumọ tọrọ idariji fun oniruuru ẹṣe lọwọ Ọlọrun. Ki ni o fa? Wọn ko ṣetan lati ronupiwada. Ẹni ti o ba ṣetan lati ronupiwada ko kan ni tọrọ idariji lọwọ Ọlọrun; yoo tun gbe igbesẹ ironupiwada pẹlu, bi Sakeu ti ṣe ṣe lọjọ ti Jesu mu igbala tọ ọ wa. Wo nkan ti a sọ nipa rẹ: “Woo, Oluwa, aabọ ohun ini mi ni mo fifun talaka; bi mo ba si fi eke gba ohun kan lọwọ ẹnikẹni, emi san an pada ni ilọpo mẹrin!” (Lúùkù 19:8) Ta lo sọ fun Sakeu pe ko fun awọn alaini ni aabọ nkan ini rẹ? Ko si! O kan mọ lọkan rẹ pe nigba ti igbala ti wọn inu aye oun wa, ọrọ̀ taye yi ko tun gbọdọ ja mọ nkankan loju oun mọ. Yatọ si iyẹn, o tun pinu lati ṣe atunṣe pẹlu gbogbo awọn ti o ti yanjẹ sẹyin ti wọn ba yọju si i. Ṣe Jesu ni o sọ pe ki o ṣe eyi? Rara o! O ṣe nitoripe o fẹ fihan pe igbala otitọ ti wọ aye oun ni. Nitorina, ti igbala ba ti wọ inu aye eniyan wa, awa kọ ni a o ma kọ ni igbesẹ ironupiwada ti o yẹ ki o gbe – yoo mọ ninu ara rẹ awọn atunṣe ti o yẹ ki o n ṣe. Njẹ iwọ naa gẹgẹ bi ẹni igbala mọ awọn atunṣe ti o yẹ ki o ṣe ninu aye rẹ ati lori awọn ibaṣepọ rẹ bi?
Ẹ̀KỌ́ LÁTI ARA JÉSÙ
Wayi o, lati ara Sakeu nikan kọ ni a ti le kẹkọ ninu akọsilẹ ipade rẹ pẹlu Jesu; a le ti ara Jesu naa kọ ẹkọ. Ki si ni awọn ẹkọ ti a le ti ara bi O ti ṣe si Sakeu lọjọ yi kọ? Lara wọn ni iwọnyi:
Rírìn nínú Ẹ̀mí mímọ́: Bibeli sọ wipe, “Bi awa ba wa laaye sipa ti Ẹmi, ẹ jẹ ki a si maa rin nipa ti Ẹmi.” (Gàlátíà 5:25) Eyi tunmọ si pe ti Ẹmi Ọlọrun ba n gbe inu wa nitootọ, nṣe ni o yẹ ki a ma fi igba gbogbo rin nipasẹ itọni rẹ. Aijẹbẹ, ọpọ nkan ni Ọlọrun ko ni le lo wa fun tabi ko le wa lọwọ. Awọn asiko naa si wa to jẹ wipe Ọlọrun ko ni i le pa wọn mọ, ti a ko ba fi ara balẹ lati ma gba itọni Ẹmi rẹ. Bawo ni Jesu ṣe mọ wipe Sakeu yoo ṣe afẹri Oun lọjọ ti a n wi yi? Nipasẹ Ẹmi Ọlọrun ni! Bawo ni O si tun ṣe mọ pe ori igi ni yoo wa nigba ti Oun ba n kọja? Nipasẹ ifihan Ẹmi Ọlọrun ni eyi naa pẹlu! Bawo si ni O ṣe mọ wipe O yẹ ki Oun pa irinajo Oun ti lati wọ si ile Sakeu? Nipasẹ ifihan ati itọni Ẹmi Ọlọrun ni! Ka lọ sọ wipe ko ri aye gbọ ohun Ọlọrun tabi gba ifihan rẹ ni asiko yi ni, o ṣeeṣe ki Ọlọrun ma ri lo rara fun irapada ọkan Sakeu ati awọn miran ti o wa ni ile rẹ lọja naa. Eyi si n jẹ ki o ye wa pe awọn kan wa ti Ọlọrun ko le lo wa fun ti ko ba ṣe pe O ba fun wa ni ifihan ti o peye nipa wọn.
Òye kókó iṣẹ́-ìránṣẹ́ wa: A tun ri wipe o ṣe pataki ki a ni oye iṣẹ-iranṣẹ ti Ọlọrun gbe le wa lọwọ. Aijẹbẹ, o ṣeeṣe ki awọn kan fi irẹwẹsi si ọkan wa, ki wọn si di wa lọwọ nipasẹ awọn ọrọ alufansa ẹnu wọn tabi nipasẹ inunibini wọn. Jesu sọ wipe: “Nitori Ọmọ Eniyan de lati wa awọn ti o nu kiri, ati lati gba wọn la.” (Lúùkù 19:10) Kilo de ti O fi sọ eyi? Idi ni pe awọn adari ẹsin awọn Juu ti n sọ wipe ki ni O n wa ni aarin awọn ẹlẹṣẹ, iyẹn awọn eniyan bi Sakeu? O wa jẹ ki o ye wọn pe awọn ẹlẹsẹ yẹn gan ni a ran Oun lati wa kiri ati lati gba la. Nitorina, ibi ti o yẹ ki O wa gan ni O wa lọjọ ti a n wi yi ati ni asiko naa pẹlu. Ti awa naa ba ni oye koko iṣẹ-iranṣẹ wa, a o ma fi igba gbogbo mọ ibi ti o yẹ ki a wa ati awọn ti o yẹ ki a ma a ba ṣe pọ. Eyi ko si ni jẹ ki a kọbiara si awọn ti o ba n sọ isọkusọ nipa iṣẹ ti Ọlọrun gbe le wa lọwọ. Amọ ṣa o, ohun yowu ti a o ba pe ni koko iṣẹ-iranṣẹ wa gbọdọ wa ni ibamu pẹlu awọn nkan ti a ri ninu bibeli. Aijẹbẹ, a le lọ kẹ pakute iku tabi ijamba fun aye wa tabi ọkan wa.
Ìgboyà: Lilọ si ile Sakeu, ẹni ti awọn eniyan mọ si gbaju-gbaja ẹlẹṣẹ ni ọjọ ti a n wi yi jẹ nkan igboya gidi fun Jesu. Ko tilẹ wo pe awọn eniyan yoo bu Oun tabi fi oju onijẹkujẹ wo Oun rara. Ki ni idi? Idi ni pe O mọ wipe ifẹ Ọlọrun ni Oun n ṣe ni asiko naa. Nitori eyi, bi ko tilẹ dun mọ awọn eniyan ninu, bi yoo tilẹ jẹ ki wọn ka si ẹni ti ko mọ nkan ti O n ṣe, O gbe igbesẹ igboya, igbesẹ akin, lati wọ ile Sakeu ati lati ba a jẹun. Eyi si yọri si igbala ọkan ati ile ọkunrin naa. Ti awa naa ba n gbe igbesẹ igboya, bi o tilẹ jẹ wipe awọn eniyan le ṣe inunibini wa, ọpọ ni Ọlọrun yoo maa ri gbala. Amọ ti a ba n wo nkan ti awọn eniyan yoo sọ si wa tabi ṣe lodi si wa, awọn nkan ti o tọna kan wa ti a le ma lailai ṣe. Ohun ti eniyan ko ba si wa ṣe fun Ọlọrun, a ko le fun ni ere fun.
ỌRỌ IPARI
Itan bi Sakeu ṣe di ẹni igbala jẹ eyi ti o wu ni lori pupọ, ti o si tun n kọ wa ni pataki ki ọkan wa ma fi igba gbogbo pongbẹ fun Ọlọrun. Ipongbẹ wa fun un le bi oniruuru iriri ti yoo yi aye wa pada titi lailai. Nitorina nṣe ni ki a ma gbadura pe ki Ọlọrun ma fi ojoojumọ kun ọkan wa pẹlu ipongbẹ otitọ ati eyi ti o peye fun un.
ÌBÉÈRÈ
– Mẹnuba awọn ẹkọ miran ti a le ti ara itan Sakeu kọ ti a ko mẹnuba ninu ẹkọ bibeli yi?
Láti ọwọ́ Johnson O. Lawal
Copyright © 2025 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)
ÀKỌ́RÍ: ÈLÍṢÀ ÀTI ÈLÍJÀ | ÀYỌKÀ: 1ÀWỌN ỌBA 19:19-21 | ỌJỌ́RÚ 22, SẸ́RẸ́ 2025
ÀKỌ́SÓRÍ: “Nigba naa Elija wi fun un pe, “Duro nibi; Oluwa ran mi lọ si Jọdani.” O si da a lohun pe, “Gẹgẹ bi o ti jẹ wipe Oluwa ye ati gẹgẹ bi o ti ye, emi ko ni fi ọ silẹ.” Bẹẹ ni awọn mejeeji si jọ n lọ.” (2Àwọn Ọba 2:6)
Ọ̀RỌ̀ ÌSÀÁJÚ
Pataki lara awọn nkan ti a fi ye ninu bibeli ni pe gbogbo awọn akọsilẹ inu iwe mimọ ni o wa lati kọ wa lẹkọ ninu ifarada ati iduroṣinṣin, ki ifẹ Ọlọrun ba a le wa si imuṣẹ ninu aye wa (Róòmù 15:4). Nitorina, gbogbo awọn ti a darukọ wọn ninu bibeli ni a le ti ara wọn kọ ẹkọ kan tabi omiran lati fi ẹṣẹ wa mulẹ ninu igbagbọ. Lara awọn ti a si sọrọ nipa wa ni Eliṣa ati Elija. Lotitọ, itan igbesi aye awọn mejeeji yi ti a kọ sinu bibeli yatọ si ara wọn. Ọpọlọpọ ẹkọ ni a si le kọ lati ara awọn itan wọnyi. Amọ, ninu ẹkọ yi, afojusun wa kọ ni lati wo igbesi aye ọkọọkan ninu awọn wolii nla yi bikoṣe lati wo nkan ti o pa awọn mejeeji pọ ati ẹkọ ti a le Ie ara eyi kọ. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun ṣi oju ẹmi wa lati ri awọn nkan ti O fẹ ki a tipasẹ ẹkọ yi ri, ki O si tun fun wa ni okun lati ṣe amulo rẹ. Amin.
ÌPÈ ÈLÍṢÀ
Nkan akọkọ, bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ti o pa Eliṣa ati Elija pọ ni ipe Eliṣa. Wolii Elija ti jẹ aṣoju Ọlọrun si orilẹ-ede Isiraẹli fun ọdọ melokan ṣaaju ipe Elija. A ko sọ fun wa ni pato iye ọdun ti o lo lati ṣiṣẹ iranṣẹ rẹ si orilẹ-ede yi. Amọ nigba ti ko diẹ ki iṣẹ iranṣẹ rẹ pari, Ọlọrun kọ si lati wa ọkunrin kan ti a n pe orukọ rẹ ni Eliṣa kan ati lati yan gẹgẹ bi wolii ti yoo rọpo rẹ. (Wo: 1Àwọn Ọba 19:15-16)
Ṣe Elija wa ṣe gẹgẹ bi Ọlọrun ti pa a laṣẹ fun tabi ko ṣe bẹ ẹ? O ma ṣe bẹ ẹ. Iwọ naa wo nkan ti a kọ nipa eyi:
“Bẹẹ ni Elija lọ kuro nibẹ, o si ri Eliṣa ọmọ Safati. O n fi ajaga maalu mejila tulẹ niwaju rẹ, ati oun naa niwaju ikejila. Elija si tọ ọ lọ, o si da agbada rẹ bo o. Nigba naa ni Eliṣa si fi awọn maluu silẹ, o si sare tọ Elija lẹyin. O wi pe, “Emi bẹ ọ, jẹ ki emi lọ fi ẹnu ko baba ati iya mi ni ẹnu. Nigba naa ni emi yoo tọ ọ lẹyin.” Elija si dahun wi pe, “Pada ṣẹyin, ki ni mo fi ṣe o?” Eliṣa si fi i silẹ, o pada ṣẹyin. O si mu ajaga maluu rẹ, o si pa wọn. O si fi ohun-elo awọn maluu naa bọ ẹran wọn, o si fi fun awọn eniyan, wọn si jẹ. Nigba naa ni o si dide lati tọ Elija lẹyin, o si ṣe iranṣẹ fun un.” (Àwọn Ọba 19:19-21)
Bi a ti ṣe ri ninu awọn ẹsẹ bibeli wọnyi, daju-ṣaka ni pe Elija gbe igbesẹ lati ṣe ifẹ Ọlọrun ni yiyan Eliṣa gẹgẹ bi wolii to yoo rọpo rẹ si orilẹ-ede Isiraẹli. Ki ni o wa fa ti o fi jẹ wipe Eliṣa ni Ọlọrun ni ki Elija yan lati rọpo rẹ gẹgẹ bi wolii si orilẹ-ede Isiraẹli? Ki ni Ọlọrun ri ninu Eliṣa ti o fi jẹ wipe oun ni O yan?
A ṣa a ri wipe agbẹ ni ni Eliṣa ṣaaju asiko ti a pe lati tẹle Elija yi, iṣẹ agbẹ ni o n ṣe. Eyi ja si pe ko ki i ṣe wolii ni asiko ti a pe. Bẹẹ si tun ni, ko si lara awọn ọmọ wolii ni asiko naa. A ni awọn ti a n pe ni awọn ọmọ wolii ni asiko ti a n sọ yi. Awọn wọnyi ni a le pe ni akẹkọ iṣẹ wolii labẹ awọn wolii agba. Eyi tunmọ si pe awọn wọnyi ri ara wọn bi awọn ti Ọlọrun pe lati jẹ wolii fun un ṣugbọn ti wọn n fẹ lati kọkọ gba ẹkọ lati ọdọ awọn ti o ti jẹ wolii ṣaaju wọn.
Yatọ si eyi, a tun ri ninu bibeli pe Elija ni iranṣẹ kan ti o n tẹle kaakiri ṣaaju asiko yi. Ki wa lo fa a ti o fi jẹ wipe Ọlọrun ko mu iransẹ yi lati rọpọ rẹ? Ati wipe ki ni o fa ti ko fi mu ọkankan ninu awọn ti o ti jẹ wolii ṣaaju Eliṣa tabi ọkankan laarin awọn ọmọ wolii ti o wa ni ilẹ Isiraẹli ni asiko yi lati rọpo Elija?
Ki a sọ otitọ, a ko fi tààrà-táárá mẹnuba awọn idi fun eyi ninu bibeli. Ṣugbọn, akọkọ, a ri wipe ẹni ti o jẹ iranṣẹ Elija ṣaaju asiko yi ko ṣetan lati tẹle titi de opin. Bibeli sọ wipe, “Elija si bẹru, o sa fun ẹmi rẹ. Nigba ti o si de Biaṣeba ti Juda, o si fi ọmọ dọ rẹ silẹ nibẹ…” (1Àwọn Ọba 19:3) Ki ni o fa ti Elija fi bẹru, ti o si tun sa fun ẹmi rẹ ni asiko yi? Nkan ti o fa ni pe Jesebẹli, ayaba Ahabu, n lepa ẹmi rẹ. Ṣe o wa yẹ ki iranṣẹ rẹ fi silẹ lati ma da salọ ni asiko yi? Ko yẹ. Nṣe ni o yẹ ki o ma tẹle ọga rẹ lọ si ibikibi ti o ba salọ. Eyi ni yoo fi i han gẹgẹ bi olufọkansi iranṣẹ. Amọ ko tẹle. Ki ni idi? A ko sọ fun wa. O ṣeeṣe ki o jẹ wipe sisalọ-sisabọ pẹlu Elija ti su u. Nitorina, nigba ti o ni ki o duro si Biaṣeba, ko ba a janpata rara. Nṣe ni o duro sibẹ. Ibi ti a si ti gburo ọkunrin yi gbẹyin ninu bibeli niyẹn – a ko tun gburo rẹ mọ lailai. Eyi n si n fi idi ọrọ Jesu mulẹ pe ẹni ti o ba foriti de opin ni a o gbala (Mátíù 24:13).
Siwaju si, Ọlọrun nikan ni Ọba ti o ri inu ati ode awọn eniyan. Nitorina, gẹgẹ bi O ti ṣe sọ fun Samuẹli nigba ti o lọ lati yan ọba ni ile Jese fun Isiraẹli, inu ni Oun ma n wo, ko ki i ṣe kiki ode bi awọn eniyan. Nitorina, ẹni ti awa eniyan le ro wipe o koju oṣuwọn fun iṣẹ Ọlọrun le ma koju oṣuwọn rara. Ẹni ti a ko wa foju si lara ni o le wa koju oṣuwọn fun iṣẹ ti Ọlọrun fẹ ẹ ṣe. Idi niyi ti a fi nilo iṣipaya tabi ifihan Ọlọrun funrarẹ lati mọ irufẹ ẹni ti ipo iṣedari tọ si, paapaa julọ ninu ijọ awọn eniyan rẹ. Aijẹbẹ, o ṣeeṣe ki a doju iṣẹ rẹ delẹ. (Wo: 1Sámúẹ́lì 16:7)
Elija ko fi aye gba ẹran ara lati lo lati yan wolii ti yoo rọpo rẹ fun Isiraẹli. Ko kan dede mu ọkan lara awọn ọmọ wolii ti o wa ni ilu lasiko naa lati rọpo ara rẹ. Nṣe ni o tẹle ifẹ ati aṣẹ Ọlọrun. Alabajọ, ti Ọlọrun fi ri Eliṣa lo lọna ti o ga lati ran orilẹ-ede Isiraẹli lọwọ ni asiko rẹ ati lati fi idi ifẹ rẹ mulẹ ni aarin wọn ati ni aarin awọn orilẹ-ede ti o yi wọn ka. Ti awa ti a jẹ adari ijọ Ọlọrun naa ba bẹrẹ si ni ṣe bẹẹ gẹgẹ, o di dandan ki ifẹ Ọlọrun ma gbilẹ si ninu ijọ rẹ lati ìran-dé-ìran.
ÀMÚYẸ ÈLÍṢÀ
O wa yẹ ki a mọ awọn nkan ti Ọlọrun ri ninu Eliṣa ti O fi ri gẹgẹ bi ẹni ti o san ju awọn ti o ti jẹ wolii ṣaaju rẹ lọ lati rọpo Elija. Pataki lara awọn nkan naa si ni iwọnyi, bi a ti ṣe ri wọn ninu bibeli:
– Ìjáfáfá: Ẹnu iṣẹ ni a ti ba Eliṣa nigba ti Elija tọ ọ wa. Lotitọ, a ri wipe ìdílé Eliṣa lowo, wọn si tun lọla. Eyi ni o fa ti wọn ni ọpọlọpọ awọn eniyan ti o n ba wọn ṣiṣẹ lasiko yi. Ajaga maalu mejila ni wọn n lo lati tu ilẹ lọjọ ti Elija wa Eliṣa dele. A si wa ri wipe, Eliṣa funrarẹ naa n lo ọkan lara awọn ajaga yi lati ṣiṣẹ. Ko wipe niwọn igba ti awọn ti ni ọpọlọpọ oṣiṣẹ, nṣe ni o yẹ ki oun maa sun tabi ṣere jade pẹlu awọn ọrẹ oun lati lọ maa ṣe faaji. Ti o ba jẹ wipe ọlẹ ati onifaaji kan ni ọkunrin yi jẹ ni, Elija ko ba ma ti ba nile tabi lẹnu iṣẹ, debi wipe yoo pe e fun iṣẹ ti Ọlọrun fẹ ẹ lo fun. Eyi si n jẹ ki o ye wa pe Ọlọrun ko ki i pe ọlẹ tabi alainikanṣe si iṣẹ iranṣẹ rẹ. Gbogbo awọn ti a ri ninu bibeli pe O pe ni o jẹ wipe ẹnu iṣẹ ni a ti ba wọn. A wa ri ọpọ ọlẹ loni ti wọn n reti ki Ọlọrun pe wọn ati lo wọn fun iṣẹ ijọba rẹ. A si tun ri ọpọ ọlẹ ati afaajọ loni ti o jẹ wipe awọn ni wọn pe ara wọn, nigba ti wọn ko rikan-ṣekan. Irufẹ awọn wọnyi ko le ṣe iṣẹ ijọba Ọlọrun bi O ti fẹ. Nṣe ni wọn yoo doju iṣẹ rẹ dele.
– Ìgbàgbọ́: Nigba ti Elija wa Eliṣa kan, ti o si da agbada rẹ bo o, lẹṣẹkẹṣẹ ni oye nkan ti eyi tunmọ si ye e. Ki si ni o tunmọ si? O tunmọ si pe Elija n sọ fun pe oun ni Ọlọrun yan gẹgẹ bi i wolii ti yoo rọpọ oun fun orilẹ-ede Israẹli. Ṣe o wa gbagbọ tabi ko gbagbọ? O gbagbọ pe bi Ọlọrun ti ṣe fẹ ni Elija ti ṣe ṣe yẹn, bi o tilẹ jẹ wipe ko si iṣẹ ami tabi ara kan ti Elija ṣe lati fi da a loju pe Ọlọrun n pe. O si fi igbagbọ rẹ han nipa pipa iṣẹ rẹ, ẹbi rẹ ati ọrọ rẹ ti lati tẹle Elija gẹgẹ bi iranṣẹ rẹ, titi asiko ifarahan rẹ si Isiraẹli yoo fi to. Eyi jasi pe ti a ba gbagbọ ninu Ọlọrun nitootọ, Oun ti O ba fẹ fun wa ni awa naa yoo ba fẹ, bi o tilẹ jẹ wipe a le tipasẹ eyi padanu owo wa, ọrọ wa, iṣẹ wa tabi awọn ibaṣepọ wa. Awọn ti o ba si ni irufẹ igbagbọ yi ni Ọlọrun ma n pe, ti O si ma n ṣe yẹ lati ṣe akanṣe iṣẹ ninu ijọba rẹ.
– Ìyára: Nkan miran ti a tun ri lara Elija ni iyara lati tẹle aṣẹ Ọlọrun. Bi a ti ṣe ri ninu awọn ẹsẹ bibeli ti o wa loke yẹn, ẹsẹkẹṣẹ ti Elija yọ si Eliṣa lati jiṣẹ fun naa ni o ti pa nkan ti o n ṣe ti lati tẹle. Lotitọ, o tọrọ aye lati dagbare fun awọn obi ati ara rẹ, ti Elija si gba fun un. Amọ eyi ko tunmọ si pe onilọra ni. Ko ki i ṣe onilọra rara. Dipo bẹẹ, ẹni ti o ṣetan lati sin Ọlọrun ni kiakia ati tọkan-tọkan ni. Ọlọrun si ri inu rẹ. Eyi si jẹ ki o yatọ si ẹni ti Jesu sọ fun pe ki o tẹle Oun, ti o si dahun pe, “Jẹ ki n kọkọ lọ dagbere fun awọn ara ile mi.” Bawo ni yoo ṣe gba a ni asiko to si lati dagbere fun awọn eniyan rẹ? A ko mọ. Ṣugbọn Jesu mọ lọkan rẹ wipe ọkunrin yi ko ti pa ọkan rẹ pọ lati tẹle Oun. Idi si ni yi ti O fi sọ fun pe, “Ko si ẹni ti o fi ọwọ rẹ le ohun elo itulẹ, ti o si wo ẹyin, ti o yẹ fun ijọba Ọlọrun.” (Wo: Lúùkù 9:61-62) Nitorina, eyi ko tunmọ si pe Jesu ko fẹ ki a to ile wa tabi iṣẹ wa ti a ba nilo lati fi wọn silẹ lati ṣiṣẹ ijọba rẹ. Ṣugbọn ko fẹ ki a ma fi oni-dọla lori iṣẹ rẹ. Aijẹbẹ, ko ni ka wa si ẹni ti O le lo lati ṣe awọn iṣẹ ijọba rẹ kan.
– Ìrẹ̀lẹ̀: A tun ri wipe Eliṣa ni ọkan irẹlẹ lati sin Elija ati lati kẹkọ lọdọ rẹ. Ki a ma gbagbe pe ni kete ti Elija da agbada rẹ bo o ni o ti mọ wipe Ọlọrun ti yan oun lati rọpo wolii yi. Eyi tunmọ si pe ti o ba fẹ da duro funrarẹ, o le ṣe bẹẹ gẹgẹ. Ti o ba si woye pe nṣe ni ki oun naa bẹrẹ iṣẹ iranṣẹ oun lẹgbẹkan, o le ṣe bẹẹ gẹgẹ. Amọ bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun ti ya a sọtọ fun iṣẹ iranṣẹ wolii ati lati rọpo Elija, agbara Ẹmi mimọ lati ṣe iṣẹ yi ko i ti ba le e. Yatọ si eyi, ko ṣe ohunkohun ti o jẹ mọ iṣẹ wolii tabi ki a waasu ri. Nitorina, ọna wo gan ni o mọ ti o n o dorikọ. Idi niyi ti o fi ṣe nilo itọni ati ifarabalẹ di asiko ti a o wọ ni agbara lati ṣe iṣẹ ti a fẹ ẹ gbe fun. Ti ko ba wa ni irẹlẹ ni, ko ni tẹle Elija lati kẹkọ ati lati duro de asiko ti a o ro ni agbara lati ipasẹ wolii yii kanna. Siwaju si, ile ọla ati ile ọrọ ni Eliṣa ti jade wa. Oun funrarẹ ni awọn iranṣẹ ti o n ba a ṣiṣẹ. Yoo wa nilo irẹlẹ lati maa tẹle wolii kan kaakiri lati jẹ iranṣẹ rẹ ati lati ma jẹ ounjẹ yowu ti o ba gbe kalẹ siwaju rẹ. Idi niyi ti a fi ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi ẹni ti o n bu omi si Elija lọwọ (2Àwọn Ọba 3:11). Awa naa nilo irẹlẹ ti a o ba ba Ọlọrun rin, ti a o si ba a ṣiṣẹ. Jesu tilẹ jẹ ki o ye wa pe ẹnikẹni ti ko ba ṣetan lati rẹ ara rẹ silẹ gẹgẹ bi iranṣẹ lati sin awọn miran ninu ijọba rẹ, ko le de ipo giga ninu ijọba naa. Nitori eyi, a ko gbọdọ jẹ ki ipo wa, ẹkọ wa, dukia wa tabi ibaṣepọ yowu ti a ni ko si wa lori debi wipe a ko ni le rẹ ara wa silẹ lati sin awọn ọmọ Ọlọrun miran tabi awọn iranṣẹ rẹ. Aijẹbẹ, igbega Ọlọrun yoo jina si wa. (Wo: Fílípì 2:5-11)
– Sùúrù ati ìrọ́jú: Yatọ si awọn nkan ti a ti mẹnuba siwaju nipa Eliṣa, a tun ri wipe o jẹ ẹnikan ti o ni suuru ati irọju. Ẹ ma gbagbe pe Elija ti ni iranṣẹ kan ri ti o fi silẹ si Biaṣeba, ti a ko si gburo rẹ mọ titi iṣẹ iranṣẹ rẹ laye fi parẹ. Bẹẹ si ni ko ba ṣe ri fun Eliṣa naa ti o ba le jẹ ẹnikan ti ko ni suuru ni. Akọkọ naa, a ko mọ bi asiko ti o lo pẹlu Elija ti ṣe pẹ to lati kẹkọ ati lati duro de igba ti a o ro ni agbara gẹgẹ bi wolii ti yoo rọpo wolii yii. Ekeji, bi a ti ṣe ri ninu bibeli, igba mẹta ọtọọtọ ni Elija sọ fun un pe ki o duro de oun ni awọn ibikan nitoripe Ọlọrun ran oun niṣẹ. Igba mẹta ọtọọtọ yi naa si Eliṣa sọ fun pe ko si nkan ti o n jẹ bẹẹ. Iyẹn jasi pe ibikibi ti o ba lọ ni oun naa yoo ba a lọ. A si wa ri wipe ọjọ yi gan ni Ọlọrun fẹ gba Elija soke, bi a ti ṣe fi han an ati awọn wolii miran ni ilẹ naa. Ti Eliṣa ba wa lọ jẹ ki irinkerindo atẹyinwa ati ti ọjọ naa suu ni, nṣe ni iba padanu agbara ti Ọlọrun fẹ ẹ fi ro lati rọpọ Elija lọjọ naa. Eyi wa n kọ wa pe a nilo suuru ati irọju ti Ọlọrun yoo ba a le ṣe wa yẹ fun awọn iṣẹ ti O fẹ ki a ṣe ati ti a o ba ri awọn nkankan gba lọwọ rẹ. Lotitọ, Ọlọrun ti le ṣeleri lati ṣe awọn nkankan fun wa tabi lati lo wa ni awọn ọna kan. Amọ ti a ko ba ni suuru ati irọju lati kẹkọ ati lati farabalẹ de asiko ti yoo ṣe iṣẹ rẹ laṣepe ninua aye wa, afaimọ ki a ma padanu nkan ti O ti pese silẹ fun wa. (Wo: 2Àwọn Ọba 2:1-6)
– Àfojúsùn: Ara nkan ti o yani lẹnu julọ ninu ibaṣepọ Elija ati Eliṣa ni pe ni ọjọ ti a n gba Elija soke ọrun, nṣe ni o tun n bere nkan ti Eliṣa fẹ ki oun ṣe fun. Ki lo de ti o bere eyi lọwọ rẹ? Ṣe o fẹ sọ wipe oun ko mọ wipe nitori ki o ba a le gba agbara fun iṣẹ-iranṣẹ rẹ ni o ṣe n tẹle oun ni? Ni oju ará-ìta, o rọrun lati sọ wipe idi ti Eliṣa ṣe n tẹle ni ki o ba a le gba ironilagbara fun iṣẹ iranṣẹ rẹ gẹgẹ bi wolii ti yoo rọpo rẹ. Ṣugbọn njẹ ko ṣeeṣe ki Eliṣa ni idi miran ti o ṣe pataki si ju eyi lọ ti o ṣe n tẹle Elija? O ṣeeṣe! Ṣe ko le jẹ nitori iyi, ọrọ tabi aifẹkanṣe ni o ṣe n tẹle bi? O le e jẹ bẹẹ. Ṣe ko tun ṣeeṣe ki o jẹ wipe afojusun rẹ ti yipada lẹyin igba ti o bẹrẹ si ni tẹle Elija? O ṣeeṣe! Lotitọ, ni ibẹrẹ-pẹpẹ, nitori ki o ba a le kẹkọ ati ki o ba a le gba ironilagbara ni o ṣe tẹlẹ Elija. Amọ, o ṣeeṣe ki idi ti o ṣe n tẹlẹ ti yipada loju ọna. Nitorina, a nilo lati bere lọwọ rẹ ni opin iṣẹ iranṣẹ Elija pe ki ni o fẹ ki a ṣe fun un. Jesu naa ti bere lọwọ afọju kan ri pe ki ni o fẹ ki Oun ṣe fun un. Idahun rẹ si ni Jesu tẹle lati mọ nkan ti yoo ṣe fun un.
A wa dupẹ lọwọ Ọlọrun pe Eliṣa ko sọ afojusun rẹ nu rara. Bi o si tilẹ jẹ wipe awọn ọmọ wolii kan tilẹ gbiyanju lati da a lẹkun lati ma tẹle Elija lọjọ ti a n wi yi, ko ma da wọn lohun tabi kọbiara si ọrọ wọn. Nkan ti o fẹ gba ni o wa lori ẹmi rẹ. Ṣe o wa ri gba tabi ko ri gba? O ma ri gba. Ta si ni o fun ni nkan naa? Ọlọrun ma ni, ko ma ki i ṣe Elija. Lotitọ, o sọ fun Elija pe oun fẹ iṣepo meji agbara rẹ, eyi to o tunmọ si ipo akọbi ninu awọn wolii. Ṣugbọn Elija naa jẹ ki o ye pe, nkan ti o bere kọja nkan ti oun le fun un. Ki ni idi? Idi ni pe Ọlọrun ni O ma n yan eniyan fun iṣẹ iranṣẹ. Ọlọrun si tun ni O ma n ro eniyan lagbara fun iṣẹ iranṣẹ. Ẹni ti ko ba wa yan, ki O si ro lagbara, ko si baba ẹni naa ti o le ro o lagbara. Eyi si n jẹ ki o ye wa pe, bi wolii tabi angẹli kan ba tilẹ sọ fun wa pe Ọlọrun fẹ lo wa, nṣe ni ki a ṣe ọkan wa yẹ fun iṣeyẹ Ọlọrun fun iṣẹ naa. Aijẹbẹ, ko si ohunkohun ti ẹnikẹni le ṣe fun wa lati ro wa lagbara tabi lati ṣe wa yẹ fun iṣẹ yowu ti a fẹ ṣe ninu ijọba Ọlọrun ti yoo ṣiṣẹ. Ara idi si niyi ti a fi gbọdọ ni afojusun ti o peye, ki a si tẹjumọ nkan ti a fẹ rigba lọwọ Ọlọrun titi yoo fi tẹ wa lọwọ. (Wo: 2Àwọn Ọba 2:7-16)
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Ni ipari, a ri lati ara ibaṣepọ Eliṣa ati Elija pe awọn amuyẹ kan wa ti a gbọdọ ni ki Ọlọrun to le ka wa si ẹni ti O le lo fun iṣẹ ijọba rẹ kankan. Ti a ko ba si ni awọn amuyẹ yi, bi o ti wu ki a tiraka to tabi lakaka to lati wulo ni ọwọ rẹ, ko ni i le lo wa fun awọn akanṣe iṣẹ iranṣẹ kan. Idi si ni yi ti gbogbo wa fi gbọdọ rẹ ara wa silẹ lati kẹkọ ninu ọrọ rẹ lori awọn nkan ti o gbọdọ wa ninu aye wa, ki a ba a le wulo fun ogo Ọlọrun.
ÌBÉÈRÈ
– Ki ni idi ti Ọlọrun ko fi ro Eliṣa ni agbara lẹsẹkẹsẹ ti O ran Elija si lati fi han gẹgẹ bi wolii ti yoo ropọ rẹ?
– Ki ni o ṣe pataki si o julọ ninu ẹkọ yi?
Láti ọ́wọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2025 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)
ÀKỌ́RÍ: RU Ẹ̀BÙN Ẹ̀MÍ RẸ SÓKÈ | ÀYỌKÀ: 2TÍMÓTÌ 1:6-7 | ỌJỌ́RÚ 08, SẸ́RẸ́ 2025
ÀKỌ́SÓRÍ: “Nitori idi eyi ni mo ṣe n ran ọ leti pe ki o maa ru ẹbun Ọlọrun soke eyi ti n bẹ ninu rẹ nipa igbọwọle mi.” (2Tímótì 1:6)
Ọ̀RỌ̀ ÌSÀÁJÚ
Bi a ti ṣe ri ninu bibeli gbogbo ọmọ Ọlọrun ni a fun ni ẹbun ẹmi kan tabi omiran (Róòmù 12:4-8; 1Kọ́ríntì 12:7&11). A si fun ẹnikọọkan wọn ni ẹbun Ẹmi yowu ti a fun wọn lati ṣe iṣẹ-isin fun imuṣẹ ifẹ Ọlọrun ninu aye awọn ọmọ rẹ ati ninu aye lapapọ. O wa ṣe pataki ki ọkọọkan ẹni ti a fun ni ẹbun ẹmi naani ẹbun naa, ki o si ma fi igba gbogbo ru wọn soke lati ṣe amulo rẹ. Aijẹbẹ yoo pa imuṣẹ ete ti Ọlọrun fi fun ni ẹbun naa lara. Ọkan pataki lara awọn nkan ti Pọọlu ba Timoti sọ ninu lẹta rẹ ekeji si ni eyi. O si wa ṣe koko ki awa naa kiyesi i ninu irin-ajo igbagbọ wa. Eyi ni ẹko bibeli yi da le lori. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun lo ẹkọ naa lati sọ ẹnikọọkan ji nibikibi ti a ba ti n sun tabi rẹwẹsi ni lilo ẹbun tabi awọn ẹbun Ẹmi ti Ọlọrun fi fun wa.
RU Ẹ̀BÙN Ẹ̀MÍ RẸ SÓKÈ
Wayi o, bi a ti ṣe ri ninu akọsori wa fun ẹkọ yi, aṣẹ ti Ọlọrun tipasẹ Pọọlu pa fun Timoti, ọmọ rẹ ninu igbagbọ, ni pe ki o ma ru ẹbun ẹmi rẹ soke. Ki ni itumọ ki a ru ẹbun Ẹmi wa soke? Akọkọ, o tunmọ si pe ki a ma fi ẹbun Ẹmi yowu ti a ni pamọ ṣugbọn ki a ma ṣe amulo rẹ. Ekeji, o tunmọ si pe ki a lo ẹbun Ẹmi wa ni ọna ti awọn eniyan yoo fi kiyesi, ti yoo si tun fi wu wọn ni ori.
Fun apẹrẹ, a sọrọ nipa ọkunrin kan ti a n pe ni Banaba ninu bibeli. Ọkunrin yi jẹ ọkan lara wọn apọsiteli igbaani. Ṣugbọn ki Jesu to ya sọtọ gẹgẹ bi apọsiteli rẹ, a ti kọkọ mọ ọn si ọmọ-itunu. Ki si ni idi? Idi ni pe o n fi igba gbogbo lo awọn ẹbun ififunni ati igbaniniyanju rẹ lọna ti o wu awọn ọmọ Ọlọrun lori. (Wo: Ìṣe Àpọ́sítélì 4:36-37)
A tun mẹnuba arabinrin kan ti a n pe ni Dọ́kásì ninu bibeli, ẹni ti o lo ẹbun ififunni rẹ lọna ti o ga debi wipe nigba ti o ku, awọn ọmọ ijọ rẹ nilo lati ranṣẹ si Peteru lati wa gbadura fun ki o le ji dide. Nigba ti o si de ibẹ, nṣe ni awọn opo ti arabinrin yi ti ran lọwọ bẹrẹ si fi lara awọn aṣọ ti o ko fun wọn han an. Eyi si ru Peteru soke lati gbadura fun un. Ọlọrun si gbọ ohun rẹ, O si da arabinrin na pada saye fun awọn ọmọ Ọlọrun. Nkan ti a n pe ni ki a ru ẹbun Ẹmi wa soke niyẹn. (Wo: Ìṣe Àpọ́sítélì 9:36-43)
O wa yẹ ki a mọ idi ti Pọọlu fi sọ fun Timoti pe ki o ru ẹbun Ẹmi rẹ soke ki awa naa ba a le mọ bi o ti ṣe ṣe pataki to fun wa lati ru ẹbun Ẹmi ti wa naa soke. Pataki lara awọn idi naa ni iwọnyi:
– Tímótì mọ ẹ̀bùn ẹ̀mí rẹ̀: Idi akọkọ ti Pọọlu ṣe sọ fun Timoti pe ko ru ẹbun ẹmi rẹ soke ni pe o mọ ẹbun Ẹmi rẹ. Ti Timoti ko ba mọ ẹbun Ẹmi ti Ọlọrun fun un ni, ko ni nitumọ ti Pọọlu ba n sọ fun pe ki o ru ẹbun Ẹmi rẹ soke. Nitorina, ti awa naa yoo ba le ru ẹbun Ẹmi yowu ti Ọlọrun fun wa soke, a kọkọ gbọdọ mọ ẹbun Ẹmi naa. Bawo wa ni a se le mọ ẹbun Ẹmi wa? Ọrọ pọ ti a le sọ lori eyi. Amọ, lara ọna ti a le gba mọ ọn ni nipasẹ ifarahan ẹbun Ẹmi naa ninu aye wa. Ọna miran ni nipasẹ isọtẹlẹ tabi iṣipaya Ẹmi mimọ ti o n pe akiyesi wa si ẹbun Ẹmi naa ti a fi fun wa. Boya ẹbun Ẹmi wa ti wa jẹyọ tabi ko i ti jẹyọ, ti a ba le fi ara wa jin fun iṣẹ isin yowu ti ọwọ wa ba ba ninu ijọ wa tabi laarin awujọ wa, ko ni pẹ rara ti awọn ẹbun ẹmi ti Ọlọrun ti fi ta wa lọrẹ yoo fi bẹrẹ si ni farahan ninu aye wa. (Wo: 1Tímótì 4:14)
– Ìfẹ́ Ọlọ́run ni fún Tímótì láti ru ẹ̀bùn Ẹ̀mí rẹ̀ sókè: Ọlọrun, bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ko ki ṣa deede fun awọn eniyan ni ẹbun ti ko ba ni ete ti O fẹ mu ṣẹ nipasẹ ẹbun naa. Nitorina, Ọlọrun n reti pe ki ẹnikọọkan ti O fun ni ẹbun Ẹmi mimọ lati lo ni ọna ti o peye, ki ifẹ rẹ lati gbe awọn eniyan rẹ ro ati lati tun aye awọn eniyan ṣe ba a le wa si imuṣẹ. (Wo: 1Kọ́ríntì 12:7; Éfésù 4:11-16)
– Ẹ̀mi Ọlọ́run ti Tímótì ní ní agbára tó láti gbé e ró: Ara idi ti Pọọlu tun ṣe sọ fun Timoti pe ko ru ẹbun Ẹmi rẹ soke ni pe Ẹmi Ọlọrun ti O fun ni ẹbun yi ṣetan lati gbe ro lati ṣe amulo ti o peye ẹbun naa. Nitori naa ko ni awawi kankan ti o le ṣe lati ma ru ẹbun Ẹmi rẹ soke. Iwọ naa wo nkan ti Pọọlu sọ fun un: “Nitori idi eyi ni mo ṣe n ran ọ leti pe ki o maa ru ẹbun Ọlọrun soke eyi ti n bẹ ninu rẹ nipa igbọwọle mi. Nitori pe Ọlọrun ko fun wa ni ẹmi ibẹru, bi ko ṣe ti agbara, ati ti ifẹ, ati ti iṣẹra-ẹni ti o ye kooro.” (2Tímótì 1:6-7) Njẹ o ri bayẹn? Gbogbo nkan ti a nilo lati ṣe amulo awọn ẹbun Ẹmi wa ni Ọlọrun ti pese fun wa nipasẹ Ẹmi Mimọ rẹ ti O n gbe inu wa. O ti pese agbara, ifẹ ati iṣẹra-ẹni ti o ye kooro fun wa nipasẹ Ẹmi rẹ. O wa ku sọwọ wa lati mura lati lo ẹbun Ẹmi yowu ti O ti fun wa lọna ti o peye, lalai ṣe awawi kankan.
– Ọlọ́run yóò bèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bí o ti ṣe lo ẹ̀bùn Ẹ̀mí náà: Bi Pọọlu ko tilẹ mẹnuba eyi ninu lẹta rẹ si Timoti, a ri kedere ninu bibeli wipe ti Ọlọrun ba fun eniyan ni nkan, yoo ma reti ki ẹni naa jẹ olotitọ ni lilo nkan naa lati mu ete ti a fi fun un ṣẹ. Idi ni yi ti Jesu ṣe fi oluwa ile kan ti o fun awọn ọmọ ọdọ rẹ mẹta ni ọwo rẹ lati ṣowo ṣe apejuwe iha ti Ọlọrun yoo kọ si gbogbo awọn ọmọ rẹ ti O fun ni ẹbun Ẹmi ti ko si ṣe olotitọ ati olododo ni lilo wọn. Nitorina, o lewu gidigidi fun wa lati ma ru ẹbun Ẹmi wa soke lọna ti o peye niwaju Ọlọrun. Adura mi ni pe ki ewu ayeraye ma ṣe wu ẹnikẹni wa. (Wo: Mátìù 25:14-30; Lúùkù 19:11-27; 1Kọrinti 4:2)
– Kí Tímótì ba à le pọ̀ si ní ìwúlò àti ìṣerere: Bi mo ti ṣe sọ siwaju, Jesu fi iha ti oluwa awọn ọmọ ọdọ kan kọ si bi wọn ti ṣe ṣe amulo awọn nkan ini rẹ ti o ko fun wọn ṣe akawe iha ti Ọlọrun naa yoo kọ si bi a bi ti ṣe lo awọn nkan ti O fun wa, paapaa julọ awọn ẹbun Ẹmi ti O fun wa. Bi akawe naa ni ti ṣe lọ, nṣe ni a gba owo lọwọ ẹni ti ko lo owo ti oluwa rẹ fun ti a si fun ẹni ti o lo tirẹ. Eyi si jẹ ki o ye wa pe awọn ti o ba n lo ẹbun Ẹmi wọn ni o lẹtọ lati reti ki Ọlọrun fun wọn ni ẹbun Ẹmi miran si, ki wọn ba a le pọ si ni iwulo ati iṣerere. Irufẹ awọn wọnyi ni ọrọ dun lẹnu wọn lati pẹ laye si tabi lati ni awọn ẹbun Ẹmi miran. Ọpọ ni o n fẹ awọn ẹbun Ẹmi ti yoo jẹ ki wọn di ilumọọka. Ṣugbọn niwọn igba ti wọn ko wulo pẹlu awọn ẹbun Ẹmi ti wọn ni lọwọlọwọ yi, wọn ko lẹtọ si ẹbun miran lati ọdọ Ọlọrun. Ọpọ naa si tun ni o fẹ pẹ laye. Ṣugbọn ki ni wọn yoo fi pipẹ laye wọn ṣe? Awọn ti o ba n gbe aye wọn lati ṣe ifẹ Ọlọrun ati lati ṣe amulo awọn nkan ti O fun wọn ni o le ma ba Ọlọrun sọrọ lori pipẹ laye lati pọ si ni iwulo si. Pọọlu sọrọ nipa eyi fun awọn ara Filipi. A si tun ri wipe ara idi ti Ọlọrun fi da Dọkasi pada si aye ni wipe wiwa laye rẹ n mu ifẹ Ọlọrun ṣe ninu aye awọn eniyan rẹ. Nitorina, ti a ba fẹ ki Ọlọrun fun wa ni ọjọ pupọ ni ile aye yi, a nilo lati ṣe amulo awọn ẹbun ti O fun wa lọna ti o peye. (Wo: Fílípì 1:21-26)
– Kí ó ba lè ru àwọn ọmọ Ọlọ́run míràn sókè: Nipa riru awọn ẹbun Ẹmi wa soke, bi ti a ti ṣe sọ siwaju, a o fun awọn ọmọ Ọlọrun miran ni iwuri lati yin Ọlọrun logo lati ara wa ati lati ru ẹbun Ẹmi ti wọn naa soke. Nigba ti Peteru gbọ ẹri ti awọn ọmọ ijọ Dọkasi jẹ lori rẹ, ori ti oun naa wu lati gbadura fun imupada si aye rẹ. Ti awa naa ba n ru ẹbun Emi yowu ti a ba ni soke, yoo mu iwuri wa fun awọn ọmọ Ọlọrun miran ni ayika wa lati ru ẹbun Ẹmi ti wọn naa soke. Eyi yoo si jẹ ki ọpọ eniyan fi ara wọn jin fun ṣiṣe ifẹ Ọlọrun. (Wo: Ìṣe Àpọ́sítélì 9:36-43)
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Pẹlu awọn nkan ti a mẹnuba wọnyi, a ri wipe o ṣe pataki ki a ma a ru awọn ẹbun Ẹmi yowu ti Ọlọrun fun wa soke nipa lilo wọn ni ọna ti o peye. Eyi yoo jẹ ki Ọlọrun le e ti ipasẹ wa fi idi ifẹ rẹ mulẹ ninu aye wa ati ninu aye ọpọ awọn eniyan.
ÌBÉÈRÈ
– Njẹ a ri idi kankan ti o peye ti ọmọ Ọlọrun kan ṣe le kọ lati ma ru ẹbun Ẹmi rẹ soke lọna ti o peye?
– Ki ni o ṣe pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi?
Lati ọwọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2025 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)
Ọ̀RỌ̀ ÌṢAÁJÚ
Bi a ti ṣe ri ninu bibeli gbogbo ọmọ Ọlọrun ni a fun ni ẹbun ẹmi kan tabi omiran (Róòmù 12:4-8; 1Kọ́ríntì 12:7&11). A si fun ẹnikọọkan wọn ni ẹbun Ẹmi yowu ti a fun wọn lati ṣe iṣẹ-isin fun imuṣẹ ifẹ Ọlọrun ninu aye awọn ọmọ rẹ ati ninu aye lapapọ. O wa ṣe pataki ki ọkọọkan ẹni ti a fun ni ẹbun ẹmi naani ẹbun naa, ki o si ma fi igba gbogbo ru wọn soke lati ṣe amulo rẹ. Aijẹbẹ yoo pa imuṣẹ ete ti Ọlọrun fi fun ni ẹbun naa lara. Ọkan pataki lara awọn nkan ti Pọọlu ba Timoti sọ ninu lẹta rẹ ekeji si ni eyi. O si wa ṣe koko ki awa naa kiyesi i ninu irin-ajo igbagbọ wa. Eyi ni ẹko bibeli yi da le lori. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun lo ẹkọ naa lati sọ ẹnikọọkan ji nibikibi ti a ba ti n sun tabi rẹwẹsi ni lilo ẹbun tabi awọn ẹbun Ẹmi ti Ọlọrun fi fun wa.
RU Ẹ̀BÙN Ẹ̀MÍ RẸ SÓKÈ
Wayi o, bi a ti ṣe ri ninu akọsori wa fun ẹkọ yi, aṣẹ ti Ọlọrun tipasẹ Pọọlu pa fun Timoti, ọmọ rẹ ninu igbagbọ, ni pe ki o ma ru ẹbun ẹmi rẹ soke. Ki ni itumọ ki a ru ẹbun Ẹmi wa soke? Akọkọ, o tunmọ si pe ki a ma fi ẹbun Ẹmi yowu ti a ni pamọ ṣugbọn ki a ma ṣe amulo rẹ. Ekeji, o tunmọ si pe ki a lo ẹbun Ẹmi wa ni ọna ti awọn eniyan yoo fi kiyesi, ti yoo si tun fi wu wọn ni ori.
Fun apẹrẹ, a sọrọ nipa ọkunrin kan ti a n pe ni Banaba ninu bibeli. Ọkunrin yi jẹ ọkan lara wọn apọsiteli igbaani. Ṣugbọn ki Jesu to ya sọtọ gẹgẹ bi apọsiteli rẹ, a ti kọkọ mọ ọn si ọmọ-itunu. Ki si ni idi? Idi ni pe o n fi igba gbogbo lo awọn ẹbun ififunni ati igbaniniyanju rẹ lọna ti o wu awọn ọmọ Ọlọrun lori. (Wo: Ìṣe Àpọ́sítélì 4:36-37)
A tun mẹnuba arabinrin kan ti a n pe ni Dọ́kásì ninu bibeli, ẹni ti o lo ẹbun ififunni rẹ lọna ti o ga debi wipe nigba ti o ku, awọn ọmọ ijọ rẹ nilo lati ranṣẹ si Peteru lati wa gbadura fun ki o le ji dide. Nigba ti o si de ibẹ, nṣe ni awọn opo ti arabinrin yi ti ran lọwọ bẹrẹ si fi lara awọn aṣọ ti o ko fun wọn han an. Eyi si ru Peteru soke lati gbadura fun un. Ọlọrun si gbọ ohun rẹ, O si da arabinrin na pada saye fun awọn ọmọ Ọlọrun. Nkan ti a n pe ni ki a ru ẹbun Ẹmi wa soke niyẹn. (Wo: Ìṣe Àpọ́sítélì 9:36-43)
O wa yẹ ki a mọ idi ti Pọọlu fi sọ fun Timoti pe ki o ru ẹbun Ẹmi rẹ soke ki awa naa ba a le mọ bi o ti ṣe ṣe pataki to fun wa lati ru ẹbun Ẹmi ti wa naa soke. Pataki lara awọn idi naa ni iwọnyi:
– Tímótì mọ ẹ̀bùn ẹ̀mí rẹ̀: Idi akọkọ ti Pọọlu ṣe sọ fun Timoti pe ko ru ẹbun ẹmi rẹ soke ni pe o mọ ẹbun Ẹmi rẹ. Ti Timoti ko ba mọ ẹbun Ẹmi ti Ọlọrun fun un ni, ko ni nitumọ ti Pọọlu ba n sọ fun pe ki o ru ẹbun Ẹmi rẹ soke. Nitorina, ti awa naa yoo ba le ru ẹbun Ẹmi yowu ti Ọlọrun fun wa soke, a kọkọ gbọdọ mọ ẹbun Ẹmi naa. Bawo wa ni a se le mọ ẹbun Ẹmi wa? Ọrọ pọ ti a le sọ lori eyi. Amọ, lara ọna ti a le gba mọ ọn ni nipasẹ ifarahan ẹbun Ẹmi naa ninu aye wa. Ọna miran ni nipasẹ isọtẹlẹ tabi iṣipaya Ẹmi mimọ ti o n pe akiyesi wa si ẹbun Ẹmi naa ti a fi fun wa. Boya ẹbun Ẹmi wa ti wa jẹyọ tabi ko i ti jẹyọ, ti a ba le fi ara wa jin fun iṣẹ isin yowu ti ọwọ wa ba ba ninu ijọ wa tabi laarin awujọ wa, ko ni pẹ rara ti awọn ẹbun ẹmi ti Ọlọrun ti fi ta wa lọrẹ yoo fi bẹrẹ si ni farahan ninu aye wa. (Wo: 1Tímótì 4:14)
– Ìfẹ́ Ọlọ́run ni fún Tímótì láti ru ẹ̀bùn Ẹ̀mí rẹ̀ sókè: Ọlọrun, bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ko ki ṣa deede fun awọn eniyan ni ẹbun ti ko ba ni ete ti O fẹ mu ṣẹ nipasẹ ẹbun naa. Nitorina, Ọlọrun n reti pe ki ẹnikọọkan ti O fun ni ẹbun Ẹmi mimọ lati lo ni ọna ti o peye, ki ifẹ rẹ lati gbe awọn eniyan rẹ ro ati lati tun aye awọn eniyan ṣe ba a le wa si imuṣẹ. (Wo: 1Kọ́ríntì 12:7; Éfésù 4:11-16)
– Ẹ̀mi Ọlọ́run ti Tímótì ní ní agbára tó láti gbé e ró: Ara idi ti Pọọlu tun ṣe sọ fun Timoti pe ko ru ẹbun Ẹmi rẹ soke ni pe Ẹmi Ọlọrun ti O fun ni ẹbun yi ṣetan lati gbe ro lati ṣe amulo ti o peye ẹbun naa. Nitori naa ko ni awawi kankan ti o le ṣe lati ma ru ẹbun Ẹmi rẹ soke. Iwọ naa wo nkan ti Pọọlu sọ fun un: “Nitori idi eyi ni mo ṣe n ran ọ leti pe ki o maa ru ẹbun Ọlọrun soke eyi ti n bẹ ninu rẹ nipa igbọwọle mi. Nitori pe Ọlọrun ko fun wa ni ẹmi ibẹru, bi ko ṣe ti agbara, ati ti ifẹ, ati ti iṣẹra-ẹni ti o ye kooro.” (2Tímótì 1:6-7) Njẹ o ri bayẹn? Gbogbo nkan ti a nilo lati ṣe amulo awọn ẹbun Ẹmi wa ni Ọlọrun ti pese fun wa nipasẹ Ẹmi Mimọ rẹ ti O n gbe inu wa. O ti pese agbara, ifẹ ati iṣẹra-ẹni ti o ye kooro fun wa nipasẹ Ẹmi rẹ. O wa ku sọwọ wa lati mura lati lo ẹbun Ẹmi yowu ti O ti fun wa lọna ti o peye, lalai ṣe awawi kankan.
– Ọlọ́run yóò bèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bí o ti ṣe lo ẹ̀bùn Ẹ̀mí náà: Bi Pọọlu ko tilẹ mẹnuba eyi ninu lẹta rẹ si Timoti, a ri kedere ninu bibeli wipe ti Ọlọrun ba fun eniyan ni nkan, yoo ma reti ki ẹni naa jẹ olotitọ ni lilo nkan naa lati mu ete ti a fi fun un ṣẹ. Idi ni yi ti Jesu ṣe fi oluwa ile kan ti o fun awọn ọmọ ọdọ rẹ mẹta ni ọwo rẹ lati ṣowo ṣe apejuwe iha ti Ọlọrun yoo kọ si gbogbo awọn ọmọ rẹ ti O fun ni ẹbun Ẹmi ti ko si ṣe olotitọ ati olododo ni lilo wọn. Nitorina, o lewu gidigidi fun wa lati ma ru ẹbun Ẹmi wa soke lọna ti o peye niwaju Ọlọrun. Adura mi ni pe ki ewu ayeraye ma ṣe wu ẹnikẹni wa. (Wo: Mátìù 25:14-30; Lúùkù 19:11-27; 1Kọrinti 4:2)
– Kí Tímótì ba à le pọ̀ si ní ìwúlò àti ìṣerere: Bi mo ti ṣe sọ siwaju, Jesu fi iha ti oluwa awọn ọmọ ọdọ kan kọ si bi wọn ti ṣe ṣe amulo awọn nkan ini rẹ ti o ko fun wọn ṣe akawe iha ti Ọlọrun naa yoo kọ si bi a bi ti ṣe lo awọn nkan ti O fun wa, paapaa julọ awọn ẹbun Ẹmi ti O fun wa. Bi akawe naa ni ti ṣe lọ, nṣe ni a gba owo lọwọ ẹni ti ko lo owo ti oluwa rẹ fun ti a si fun ẹni ti o lo tirẹ. Eyi si jẹ ki o ye wa pe awọn ti o ba n lo ẹbun Ẹmi wọn ni o lẹtọ lati reti ki Ọlọrun fun wọn ni ẹbun Ẹmi miran si, ki wọn ba a le pọ si ni iwulo ati iṣerere. Irufẹ awọn wọnyi ni ọrọ dun lẹnu wọn lati pẹ laye si tabi lati ni awọn ẹbun Ẹmi miran. Ọpọ ni o n fẹ awọn ẹbun Ẹmi ti yoo jẹ ki wọn di ilumọọka. Ṣugbọn niwọn igba ti wọn ko wulo pẹlu awọn ẹbun Ẹmi ti wọn ni lọwọlọwọ yi, wọn ko lẹtọ si ẹbun miran lati ọdọ Ọlọrun. Ọpọ naa si tun ni o fẹ pẹ laye. Ṣugbọn ki ni wọn yoo fi pipẹ laye wọn ṣe? Awọn ti o ba n gbe aye wọn lati ṣe ifẹ Ọlọrun ati lati ṣe amulo awọn nkan ti O fun wọn ni o le ma ba Ọlọrun sọrọ lori pipẹ laye lati pọ si ni iwulo si. Pọọlu sọrọ nipa eyi fun awọn ara Filipi. A si tun ri wipe ara idi ti Ọlọrun fi da Dọkasi pada si aye ni wipe wiwa laye rẹ n mu ifẹ Ọlọrun ṣe ninu aye awọn eniyan rẹ. Nitorina, ti a ba fẹ ki Ọlọrun fun wa ni ọjọ pupọ ni ile aye yi, a nilo lati ṣe amulo awọn ẹbun ti O fun wa lọna ti o peye. (Wo: Fílípì 1:21-26)
– Kí ó ba lè ru àwọn ọmọ Ọlọ́run míràn sókè: Nipa riru awọn ẹbun Ẹmi wa soke, bi ti a ti ṣe sọ siwaju, a o fun awọn ọmọ Ọlọrun miran ni iwuri lati yin Ọlọrun logo lati ara wa ati lati ru ẹbun Ẹmi ti wọn naa soke. Nigba ti Peteru gbọ ẹri ti awọn ọmọ ijọ Dọkasi jẹ lori rẹ, ori ti oun naa wu lati gbadura fun imupada si aye rẹ. Ti awa naa ba n ru ẹbun Emi yowu ti a ba ni soke, yoo mu iwuri wa fun awọn ọmọ Ọlọrun miran ni ayika wa lati ru ẹbun Ẹmi ti wọn naa soke. Eyi yoo si jẹ ki ọpọ eniyan fi ara wọn jin fun ṣiṣe ifẹ Ọlọrun. (Wo: Ìṣe Àpọ́sítélì 9:36-43)
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Pẹlu awọn nkan ti a mẹnuba wọnyi, a ri wipe o ṣe pataki ki a ma a ru awọn ẹbun Ẹmi yowu ti Ọlọrun fun wa soke nipa lilo wọn ni ọna ti o peye. Eyi yoo jẹ ki Ọlọrun le e ti ipasẹ wa fi idi ifẹ rẹ mulẹ ninu aye wa ati ninu aye ọpọ awọn eniyan.
ÌBÉÈRÈ
– Njẹ a ri idi kankan ti o peye ti ọmọ Ọlọrun kan ṣe le kọ lati ma ru ẹbun Ẹmi rẹ soke lọna ti o peye?
– Ki ni o ṣe pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi?
Lati ọwọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2025 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876).
ÀKỌ́RÍ: ÍDÁMẸ́WÀÁ | ÀYỌKÀ: DITARONOMI 14:22-29 | ỌJỌ́RÚ 23, Ọ̀WÀRÀ 2024
ÀKỌ́SÓRÍ: “Ẹ ri i daju pe ẹ n fi ida kan ninu mẹwaa ninu ire oko yin lọdọọdun pamọ si apakan.” (Ditarónómì 14:22)
Ọ̀RỌ̀ ÌSÀÁJÚ
Ki ni idamẹwaa? Bawo ni o ti ṣe ṣẹ? Aṣẹ wo ni a pa fun awọn iru ọmọ Israẹli lori idamẹwaa? Aṣẹ wo ni a pa fun awọn ọmọ Ọlọrun nipasẹ igbagbọ ninu Kirisiti lori rẹ? Njẹ ègún n bẹ lori ẹni ti ko ba san idamẹwaa bi? Ki gan an ni ifẹ Ọlọrun fun wa loni lori idamẹwaa? Awọn nkan ti a fẹ gbe yẹwo ninu ẹkọ yi niyi. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun fun wa ni oye ti o peye lori ẹkọ naa, ki a ba le e ma mu ohun gbogbo ti o jẹ ifẹ rẹ fun wa ṣẹ. Amin.
KÍ NI ÌDÁMẸ́WÀÁ?
Ki ni idamẹwaa? Idamẹwaa jẹ ida kan ninu idasimẹwaa awọn nkan ti eniyan ba ni tabi ba ko lọwọ. Bawo wa ni o ṣe di ede ti a n fi igba gbogbo pe ni aarin awọn ọmọ Ọlọrun? O di ede ti a n fi igba gbogbo pe ni aarin wa nipasẹ oniruuru akọsilẹ lori awọn ti o fun Ọlọrun ni idamẹwaa ati aṣẹ Ọlọrun lori rẹ si awọn eniyan rẹ. Yatọ si eyi, o tun jẹ ọkan lara awọn nkan ti o ṣaba ma n fa ariyanjiyan laarin awọn ọmọ Ọlọrun. Nitorina, oye ohun ti o jẹ ati iha ti o yẹ ki a kọ si i ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun yẹ ki o ye wa.
Ti a ba wa fẹ ni oye ti o ye kooro lori idamẹwaa ati iha ti o yẹ ki a kọ si i ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun, a nilo lati fi ara balẹ wo nkan ti Ẹmi Mimọ sọ fun wa lori rẹ ninu bibeli, ki a si dirọ mọ ọn, bi o tilẹ yatọ si awọn nkan ti a ti kọ wa tabi gbagbọ lori rẹ tẹlẹtẹlẹ. Ki wa ni bibeli sọ lori idamẹwaa? Awọn nkan ti o sọ lori rẹ ṣe diẹ. Amọ awọn ti o ṣe pataki julọ lara wọn ni o ni i ṣe pẹlu ipilẹ idamẹwaa, ofin lori idamẹwaa, irufẹ idamẹwaa ti o wa ati nkan ti idamẹwaa n tọka si fun awọn eniyan Ọlọrun.
ÌPÌLẸ̀ ÌDÁMẸ́WÀÁ
Ki a wa ti ibi pẹlẹbẹ mu ọlẹ jẹ, ki a bẹrẹ lati ori ipilẹ idamẹwaa. Ibo ni o ti ṣẹ wa? Ta ni o kọkọ ṣan idamẹwaa? Ta ni ẹni naa fun un? Ta ni o pa laṣẹ fun un lati fun ẹni naa? Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, Aburahamu ni ẹni akọkọ ti a ri ka ninu bibeli pe o san idamẹwaa. Iwọ naa wo nkan ti a kọ silẹ lori eyi:
“Nigba ti Aburamu ti ṣẹgun Kẹdolaomeri ati awọn ọba ti o pẹlu rẹ, ọba Sodomu lọ pade e rẹ ni afonifoji Safẹ (eyi ti o tumọ si Afonifoji ọba). Melkisedeki ọba Salẹmu (Jẹrusalẹmu) si mu ounjẹ ati ọti waini jade wa. Oun ni alufaa Ọlọrun, ọga ogo. O si sure fun Aburamu wi pe, “Ibukun ni fun Aburamu lati ọdọ Ọlọrun ọga ogo ti o da ọrun oun aye. Ibukun si ni fun Ọlọrun ọga ogo julọ ti o fi awọn ọta rẹ le ọ lọwọ.” Aburamu si fun un ni idamẹwaa ohun gbogbo.” (Jẹ́nẹ́sísì 14:17-19)
Njẹ o ri bayẹn pe Aburamu ni ẹni akọkọ ti bibeli tọkasi pe o san idamẹwaa. O ṣeeṣe ki a ri awọn miran ti wọn ti san idamẹwaa ṣaaju rẹ o. Amọ, ninu bibeli, oun ni ẹni akọkọ ti o san idamẹwaa. Alufaa Ọlọrun kan ni a si sọ wipe o san an fun. Melkisedeki ni a pe orukọ alufaa Ọlọrun yi.
Bawo wa ni ti Melkisedeki ṣe jẹ ti Aburamu fi fun ni idamẹwaa? Ki tilẹ lo ṣokunfa bi o ti ṣe fun ni idamẹwaa? Akọkọ naa, a ri wipe Aburamu ṣẹṣẹ pade ti oju ogun de ni asiko ti a n sọ yi ni. Melkisedeki si ni ẹni akọkọ ti o wa pade rẹ lati ki i ati lati fi ogo fun Ọlọrun lori iṣẹgun rẹ. O tilẹ tun mu ounjẹ ati waini lọwọ fun ajọyọ pẹlu Aburamu. Bawo wa ni tirẹ ṣe jẹ?
Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, a ko sọ ọrọ pupọ lori ẹni ti ọkunrin jẹ ni abala iwe Jẹnẹsisi ti a ti kọkọ sọrọ rẹ kọja wipe o jẹ Alufaa Ọlọrun alaaye ati pe o jẹ Ọba Salẹmu. Ṣugbọn ninu iwe Heberu, ori ikeje, a jẹ ki o ye wa pe orukọ rẹ tunmọ si Ọba Ododo. A tun pe e ni Ọba Salẹmu, iyẹn Ọba alaafia. Yatọ si eyi, a jẹ ki o ye wa pe Alufaa Ọlọrun yi i ko ni iya tabi baba, ko si tun ni ibẹrẹ aye tabi opin aye. Iyẹn tunmọ si pe Alufaa Ọlọrun ni titi lailai ati wipe ko ki i ṣe eniyan tabi angẹli bikoṣe ifarahan Ẹmi Ọlọrun funrarẹ. (Wo: Hébérù 7:1-3)
Nibo wa ni Aburamu ti ba ẹni yi i pade? A ko sọ fun wa. A kan jẹ ki o ye wa pe o sure fun Aburamu ni ọjọ ti a n wi yi ati wipe Aburamu naa wa fun un ni idamẹwaa gbogbo ikogun ti o ri lẹyin igba ti o jagun gba Lọọti ati awọn ara Sodomu silẹ tan. Ta wa lo sọ fun Aburamu pe ko fun ẹni yi ni idamẹwaa ikogun rẹ? Ko si. O kan mọn ninu ọkan rẹ pe o yẹ ki oun ṣe bẹ ẹ ni. O kan mọ ni wipe o yẹ ki oun fun iriju Ọlọrun ti o tọ oun wa ni idamẹwaa gbogbo ere ogun rẹ lati mọ riri oore ti Ọlọrun ṣe fun un.
Nitorina, ifarahan fifunni ni idamẹwaa ti a kọkọ ri ninu bibeli ko ni i ṣe pẹlu aṣẹ Ọlọrun tabi ofin rẹ. Dipo bẹẹ, o ni i ṣe pẹlu ifihan ifẹ rẹ si ọkan ẹniyan. Ki si ni ifẹ yi? Oun naa ni pe o yẹ ki a ma fi tọkan-tọkan mọ riri didara rẹ si wa nipa fifun-un ni ida ti o jọju laara awọn nkan ti O ba fi ta wa lọrẹ.
Ibi keji ti a tun ti ri ifarahan idamẹwaa ninu bibeli ni eyi:
“Nigba ti Jakọbu ji loju oorun rẹ, o ro ninu ara rẹ pe, “Dajudaju Oluwa n bẹ ni ihin yii, emi ko si mọ.” Ẹru si ba a, o si wi pe, “Ihin yii ni ẹru gidigidi; Ibi ki i ṣe ibomiran bi ko ṣe ile Ọlọrun, ani ẹnu ibode ọrun niyii.” Jakọbu si dide ni kutukutu owurọ, o si gbe okuta ti o fi ṣe irọri lele bi òpó, o si da ororo si lori. O si pe orukọ ibẹ ni Bẹtẹli (Ile Ọlọrun) bi o tilẹ jẹ pe ilu naa n jẹ Lusi tẹlẹ ri. Jakọbu si jẹ ẹjẹ nibẹ pe, “Bi Ọlọrun yoo ba wa pẹlu mi, ti yoo si pa mi mọ ni irinajo mi ti mo n lọ, ti yoo si fun mi ni ounjẹ lati jẹ ati aṣọ lati wọ, ti mo si pada sile baba mi ni alaafia, nigba naa Oluwa ni yoo jẹ Ọlọrun mi, Okuta yii ti mo gbe kalẹ bi ọwọn yoo jẹ ile Ọlọrun, gbogbo ohun ti O ba si fun mi, emi yoo fun Ọ ni idamẹwaa rẹ.”” (Jẹ́nẹ́sísì 28:16-22)
Ta ni o sọ wipe oun yoo fun Ọlọrun ni idamẹwaa ninu awọn ẹsẹ bibeli yi? Jakọbu ni! Ki lo fa ti o fi fẹ fun Ọlọrun ni idamewaa? Ṣe Ọlọrun lo pa a lasẹ fun pe ki o ṣe bẹ ẹ ni? Rara o! Ọlọrun kan fi ara rẹ han ni ọjọ ti a n wi yi ni loju oorun. Nigba ti o si ji, o woye pe o yẹ ki o n juba Ọlọrun ti O fi ara rẹ han an. Idi niyi ti o fi ru ẹbọ ororo si, ti o si wa jẹjẹ pe ti Ọlọrun ba le mojuto oun, ki O si tun mu oun pada layọ wa si ile baba oun lẹyin irinajo ti o n rin, oun yoo fun ni idamẹwaa ohun gbogbo ti oun ba ni.
Iyatọ wo ni o wa wa laarin idamẹwaa ti Jakọbu ati ti Aburamu? Iyatọ akọkọ ti o wa nibẹ ni pe idamẹwaa ti Aburamu jẹ eyi ti o fun alufa Ọlọrun ti o fojuri, nigbati idamẹwaa ti Jakọbu jẹ ẹjẹ si Ọlọrun airi. A ko wa sọ ọna ti Jakọbu gba san ẹjẹ naa tabi asiko ti o san an ninu bibeli. Ṣugbọn a mọ wipe o di dandan fun un lati san an nitoripe Ọlọrun pa a mọ nitootọ, O si tun mu pada wa sile layọ.
Iyatọ keji ti o wa laarin idamẹwaa Jakọbu ati Aburamu ni pe nigbati Aburamu san idamẹwaa tirẹ lori kiki ikogun rẹ lẹyin igba ti o jagun-ṣẹgun ọba Kẹdolaomeri, Jakọbu pinu lati ṣan idamẹwaa tirẹ lori gbogbo nkan ti o ba ko pada wa sile gẹgẹ bi ini ati dukia rẹ lẹyin irinajo rẹ. Eyi jasi pe idamẹwaa ti Aburamu san ko ki i ṣe lori gbogbo nkan ti o ni. Bẹẹ si ni idamẹwaa ti Jakọbu san naa ko ki i ṣe lori gbogbo nkan ti o ti ni sẹyin ki o to rin irinajo lọ sọdọ Labani tabi lori awọn nkan ti o pada ni lẹyin igba ti o pada ti ọdọ Labani de e. Dipo eyi, o da lori kiki nkan ti o ri kojọ nigba ti o n ṣe atipo ni ile Labani.
Eyi si jẹ ki o ye wa pe awọn eniyan yii ko san idamẹwaa ni gbogbo igba tabi lọdọọdun tabi loṣooṣu tabi lọsọọsẹ. Dipo bẹẹ, wọn san bi o ti ṣe wa si wọn lọkan ni ati ni asiko ti o wa si wọn lọkan. Nitorina, ati Jakọbu ati Aburamu, ko si eyi ti Ọlọrun paṣẹ idamẹwaa fun ninu wọn. O kan wa lati inu ọkan awọn mejeeji lati fun ni idamẹwaa ni. Eyi si jasi pe, ni ibẹrẹpẹpẹ, idamẹwaa jẹ nkan ti awọn eniyan n fun Ọlọrun lati inu ọkan wọn wa. Wọn si n fun un nitori pe wọn oye ye wọn ninu ọkan wọn pe Ọlọrun jẹ ẹni ti o yẹ ki wọn ma fi nkan ini wọn bu ọla fun. Bi o si ṣe yẹ ki o ri niyi. Ohunkohun ti a ba fun Ọlọrun, yala idamẹwaa ni tabi ọrẹ, gbọdọ jẹ eyi ti a n fi fun un lati inu ọkan wa wa dipo afẹkunṣe. Bẹẹni, o gbọdọ jẹ nkan ti a fifun un nitoripe oye ye wa pe o tọna fun wa lati ma bu ọla ati iyi fun un pẹlu nkan ini wa.
ÌDÁMẸ́WÀÁ LÁBẸ́ ÒFIN MÓSÈ
Òfin ìdámẹ́wàá
Wayi o, lẹyin awọn apẹrẹ meji pere yi ti a ri ninu iwe Jẹnẹsisi lori sisan idamẹwaa, a ko ri akọsilẹ tabi aṣẹ tabi ikilọ miran mọ lori rẹ titi a fi ko awọn ọmọ Isiraẹli jade kuro loko ẹru. Lẹyin igba ti a ko wọn jade tan, ti Ọlọrun si ba wọn da majẹmu lati jẹ Ọlọrun wọn, ki wọn ba a le jẹ eniyan rẹ, ni a tun to gburo ọrọ lori idamẹwaa. Asiko yi si wa ni a fi idamẹwaa sisan lọlẹ fun awọn ọmọ Isiraẹli. Iwọ naa wo diẹ lara awọn aṣẹ ti Ọlọrun pa fun wọn lori rẹ:
“‘Gbogbo idamẹwaa ilẹ naa yala ti eso ilẹ ni, tabi ti eso igi, ti Oluwa ni. Mimọ ni fun Oluwa. Bi ẹnikẹni ba fẹ ra idamẹwaa nnkan rẹ pada: o gbọdọ fi marun-un kun un. Gbogbo idamẹwaa agbo ati ẹran ọsin, ani idamẹwaa ẹran to ba kọja labẹ ọpa-darandaran ki o jẹ mimọ fun Oluwa. Eniyan ko gbọdọ wadii boya o dara tabi ko dara, ko si gbọdọ paarọ rẹ. Bi o ba paarọ rẹ: ati eyi ti o paarọ ati eyi to fi paarọ ni ki o jẹ mimọ. Wọn ko gbọdọ ra a pada.’ Awọn aṣẹ wọnyi ni Oluwa pa fun Moṣe fun awọn ọmọ Isirẹli ni ori oke Sinai.” (Lẹ̀fítíkù 27:30-34)
Njẹ o ri bayi pe aṣẹ ni awọn nkan ti a kọ silẹ yi jẹ fun awọn ọmọ Isiraẹli lati ọdọ Ọlọrun. Aṣẹ lori kini? Aṣẹ lori idamẹwaa ni. Ki ni Ọlọrun ni ki wọn san idamẹwaa le lori? O ni ki wọn san idamẹwa lori gbogbo nkan oko wọn ati lori gbogbo nkan ọsin wọn. Lọna wo ni ki wọn gba a ya a sọtọ? Bi a ti ṣe ri ka ninu awọn ẹsẹ bibeli yi, wọn yoo ma a ka awọn nkan oko wọn ati nkan ọsin wọn ni ẹyọkọọkan de ori ikẹwa. Ikẹwa, eyi yowu ti o le jẹ, oun ni wọn yoo ya sọtọ gẹgẹ bi idamẹwaa fun Oluwa. Lotitọ, ere oko tabi nkan ọsin ikẹwa yi le ma dara. Amọ wọn ko ni anfaani lati paarọ rẹ. Ẹni ti o ba si wa wo pe oun ko le fun Ọlọrun ni idamẹwaa ti ko dara, ti o si fẹ paarọ rẹ, gbọdọ fi ati idamẹwaa ati eyi ti o fẹ ẹ fi paarọ rẹ silẹ fun Ọlọrun. Ofin idamẹwaa ni eyi.
Oríṣìríṣìí ìdámẹ́wàá
Ọna wo wa ni awọn ọmọ Isiraẹli ni lati gba lati san idamẹwaa wọn ati wipe tani o yẹ ki wọn san fun? Fun ọpọlọpọ ọdun ni ọpọ awọn onka bibeli fi gbagbọ pe gbogbo idamẹwaa ti awọn ọmọ Isiraẹli ba san ti awọn alufaa ati awọn ọmọ Lefi ni. Bẹẹ si ni a ri awọn abala bibeli ti o tọka si pe ti awọn alufaa ati awọn ọmọ Lefi ni awọn idamẹwaa ti awọn ọmọ Isiraẹli ba mu wa. Amọ bi a tun ti ṣe ri ni awọn abala bibeli miran, ko ki i ṣe gbogbo idamẹwaa naa ni o jẹ ti awọn alufaa ati awọn ọmọ Lefi.
Nitorinaa, ki a to le sọ pato ẹni ti o yẹ ki awọn ọmọ Isiraẹli fun ni idamẹwaa wọn ati ọna ti wọn yoo gba fun wọn, a nilo lati mọ oriṣi idamẹwaa ti o wa tabi ti Ọlọrun pa laṣẹ fun awọn ọmọ Isiraẹli. Oriṣi idamẹwaa melo ni o wa wa? Oriṣi idamẹwaa meji ni o wa. Akọkọ, eyi ti ọpọ eniyan si mọ daju, ni idamẹwa ti awọn alufaa ati awọn ọmọ Lefi n gba. Wo diẹ lara awọn nkan ti a sọ nipa eyi ninu bibeli:
“Oluwa sọ fun Aroni pe, “O ko ni ni ogun ninu ilẹ wọn bẹẹ ni iwọn ko ni ni ipin laarin wọn, Emi ni ipin ati ogun rẹ laarin awọn ọmọ Isirẹli. Mo ti fun awọn ọmọ Lefi ni gbogbo idamẹwaa ni Isirẹli gẹgẹ bi ogun fun iṣẹ ti wọn ṣe, nigba ti wọn n ṣiṣẹ nibi agọ ipade. Lati isinsinyii awọn ọmọ Isirẹli ko gbọdọ sunmọ agọ ipade, bi wọn ba ṣe bẹẹ wọn yoo jẹ iya ẹṣẹ wọn, wọn a si ku. Awọn ọmọ Lefi ni o gbọdọ ṣe iṣẹ ti o wa ninu agọ ipade, wọn yoo si jiya ẹṣẹ wọn bi wọn ba kuro lati ṣe e. Eyi ni ilana laelae fun awọn iran ti o n bọ. Wọn ko ni gba ogun kankan laarin awọn ọmọ Isirẹli. Kaka bẹẹ, mo fun awọn ọmọ Lefi gẹgẹ bi ogun wọn, ida kan ninu ida mẹwaa ti awọn ọmọ Isirẹli pese gẹgẹ bi ọrẹ si Oluwa. Eyi ni mo wi nipa wọn: Wọn ko ni gba ogun kankan laarin awọn ọmọ Isirẹli.” (Nọ́ḿbà 18:20-24)
“Sọ fun awọn ọmọ Lefi ki o si wi fun wọn pe: Nigba ti idamẹwaa ba n wọle lati ọdọ awọn ọmọ Isirẹli gẹgẹ bi ogun rẹ. O gbọdọ mu idamẹwaa lara rẹ gẹgẹ bi ọrẹ Oluwa. Bayi ni iwọ gan an naa yoo mu ọrẹ wa fun Oluwa lati ara idamẹwaa ti iwọ gba lati ọdọ awọn ọmọ Isirẹli. Lati ara idamẹwaa o gbọdọ mu ọrẹ Oluwa fun Aroni alufaa. Iwọ gbọdọ mu wa gẹgẹ bi ipin Oluwa eyi ti o dara julọ ati ti o jẹ mimọ julọ lara gbogbo nnkan ti wọn mu wa fun ọ.” (Nọ́ḿbà 18:26-29)
Pẹlu awọn nkan ti a ri ninu awọn ẹsẹ bibeli yi, awọn idamẹwaa ti awọn ọmọ Isiraẹli ba mu wa gbọdọ lọ si ọdọ awọn ọmọ Lefi. Idi si ni pe Ọlọrun ya wọn sọtọ fun iṣẹ ninu agọ rẹ, ko si fun wọn ini ni aarin awọn ọmọ Isiraẹli. Awọn naa tun wa gbọdọ ya idamẹwaa laara eyi ti wọn ba gba lọwọ ọmọ Isiraẹli sọtọ fun Ọlọrun. Eyi ni yoo si jẹ ti awọn alufaa ti o wa laarin wọn.
Amọ ṣa o, bi mo ti ṣe sọ siwaju, eyi ko tunmọ si pe gbogbo idamẹwaa ti awọn ọmọ Isiraẹli ba gba jọ naa ni o gbọdọ lọ si ọdọ awọn ọmọ Lefi ati awọn alufaa wọn. A tun ni oriṣi idamẹwaa miran, eyi si ni idamẹwaa ti awọn ọmọ Isiraẹli ni lati jẹ niwaju Ọlọrun. Iwọ naa wo nkan ti bibeli sọ lori eyi:
“Ki iwọ ki o ma ṣe jẹ idamẹwaa oka rẹ ninu ibode rẹ tabi ti waini rẹ, tabi ti ororo rẹ, tabi ti akọbi ọwọ-ẹran rẹ, tabi ti agbo-ẹran rẹ, tabi ti ẹjẹ rẹ ti iwọ jẹ, tabi ẹbọ ifẹ-atinuwa rẹ, tabi ẹbọ igbesọsoke rẹ. Bi ko ṣe ki iwọ ki o jẹ wọn niwaju Oluwa Ọlọrun rẹ, ni ibi ti Oluwa Ọlọrun rẹ yoo gbe yan, iwọ ati ọmọ rẹ ọkunrin ati ọmọ rẹ obinrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, ati ọmọ Lefi ti n bẹ ninu ibode rẹ: ki iwọ ki o si maa yọ niwaju Oluwa Ọlọrun rẹ ninu ohun gbogbo ti iwọ fi ọwọ rẹ le. Maa ṣọ ara rẹ ki iwọ ki o ma ṣe kọ ọmọ Lefi silẹ ni gbogbo ọjọ rẹ lori ilẹ.” (Ditarónómì 12:17-19)
“Ki iwọ ki o da idamẹwaa gbogbo ibisi irugbin rẹ, ti n ti oko rẹ wa ni ọdọọdun. Niwaju Oluwa Ọlọrun rẹ, ni ibi ti oun o gbe yan lati fi orukọ rẹ si ni ki iwọ ki o si maa jẹ idamẹwaa ọka rẹ, ti waini rẹ, ati ti ororo rẹ, ati akọbi ọwọ ẹran rẹ, ati ti agbo ẹran rẹ, ki iwọ ki o le maa kọ lati bẹru Oluwa Ọlọrun rẹ nigba gbogbo. Bi ọna ba si jin ju fun ọ, ti iwọ ki yoo fi le ru u lọ, tabi bi ibi ti Oluwa Ọlọrun rẹ yoo yan lati fi orukọ rẹ si ba jin ju fun ọ, nigba ti Oluwa Ọlọrun rẹ ba bukun ọ: njẹ ki iwọ ki o yi i si owo, ki iwọ ki o si di owo naa ni ọwọ rẹ, ki o si lọ si ibi naa ti Oluwa Ọlọrun rẹ yoo yan. Ki iwọ ki o si na owo naa si ohunkohun ti ọkan rẹ ba fẹ, si akọ maalu, tabi agutan, tabi waini, tabi ọti lile kan, tabi si ohunkohun ti ọkan rẹ ba fẹ: ki iwọ ki o si maa jẹ nibẹ niwaju Oluwa Ọlọrun rẹ, ki iwọ ki o si maa yọ, iwọ, ati awọn ara ile rẹ. Ati ọmọ Lefi ti n bẹ ninu ibode rẹ; iwọ ko gbọdọ kọ ọ silẹ; nitori ti ko ni ipin tabi ini pẹlu rẹ. Ni opin ọdun mẹta ni ki iwọ ki o mu gbogbo idamẹwaa ibisi rẹ wa ni ọdun naa, ki iwọ ki i o si gbe kalẹ ninu ibode rẹ. Ati ọmọ Lefi, nitori ti ko ni ipin tabi ini pẹlu rẹ, ati alejo, ati alaini-baba, ati opo, ti n bẹ ninu ibode rẹ, yoo wa, wọn o si jẹ, wọn o si yo; ki Oluwa Ọlọrun rẹ ki o le bukun fun ọ ninu gbogbo iṣẹ ọwọ rẹ ti iwọ n ṣe.” (Ditarónómì 14:22-29)
“Nigba ti iwọ ba da idamẹwaa ire oko rẹ tan ni ọdun kẹta, ti i ṣe ọdun idamẹwaa, ti iwọ si ti fun ọmọ Lefi, alejo, alainibaba, ati opo ki wọn maa jẹ ni ẹnu bode rẹ, ki wọn si yo; Nigba naa ni ki iwọ ki o wi niwaju Oluwa Ọlọrun rẹ pe, Emi ti mu ohun ọwọ kuro ninu ile mi, mo si ti fi wọn fun ọmọ Lefi, ati fun alejo, ati fun alaini baba, at fun opo, gẹgẹ bi gbogbo aṣẹ rẹ ti iwọ ti pa fun mi: emi ko re aṣẹ rẹ kọja, bẹẹ ni emi ko gbagbe wọn.” (Ditarónómì 26:12-13)
Ki ni awọn nkan ti a fi ẹsẹ wọn mulẹ fun wa lori idamẹwaa ninu awọn ayọka ẹsẹ bibeli wọnyi? Akọkọ naa ni pe ko ki i ṣe gbogbo idamẹwaa naa ni Ọlọrun ni ki wọn ma fun awọn ọmọ Lefi. Lotitọ, Ọlọrun ko fẹ ki awọn ọmọ Isiraẹli gbagbe awọn ọmọ Lefi wọnyi rara. Idi si ni pe wọn ko ni ipin tabi ini laarin wọn. Yatọ si eyi, bi mo ti ṣe sọ siwaju, Ọlọrun ti ya wọn sọtọ fun iṣẹ isin ti o ni i ṣe pẹlu agọ tabi tẹmupili rẹ. Nitorina, ebi ko gbọdọ pa wọn.
Amọ ko ki i wa ṣe gbogbo idamẹwaa naa ni a fi fun wọn. Bi a ti ṣe ri ninu awọn ẹsẹ bibeli ti o wa loke yi, ọdun kẹta-kẹta nikan ni a pa a lasẹ fun awọn ọmọ Isiraẹli lati ma ko gbogbo idamẹwaa wọn wa fun awọn ọmọ Lefi ati awọn alejo ati awọn alaini ati awọn opo ti o wa ni ilẹ naa. Eyi jasi pe ti a ba ti gba gbogbo idamẹwaa orilẹ-ede jọ tan ni ọdun kẹta-kẹta, awọn ọmọ Lefi ti o n ṣe amojuto rẹ gbọdọ ri daju pe awọn nikan kọ ni wọn pin laarin ara wọn. Wọn tun gbọdọ pin fun awọn alaini, awọn opo ati awọn alejo ti ko ri jajẹ ti o wa ni aarin wọn.
Ki wa ni ki awọn ọmọ Isiraẹli ṣe pẹlu awọn idamẹwaa ti wọn ba kojọ ni awọn ọdun ti o la awọn ọdun kẹta-kẹta wọnyi laarin? Aṣẹ Ọlọrun fun wọn ni pe ki wọn jẹ awọn idamẹwaa yi niwaju Oun ni ibi ti Oun yoo yan fun wọn lati ma jọsin. A si ri wipe Jerusalẹmu ni Ọlọrun yan fun wọn nigbẹyin-gbẹyin gẹgẹ bi ibi ti wọn yoo ti ma a jọsin rẹ. Nitorina, ibẹ ni gbogbo wọn yoo ma a lọ ni ọdọọdun pẹlu idamẹwaa wọn lati jẹ tayọtayọ niwaju Ọlọrun. Ọlọrun tilẹ sọ fun wọn pe awọn ti idamẹwaa wọn ba pọju lati gbe lọ si ibi ti O yan yi le ta a, ki wọn sọ di owo. Owo yii ni wọn yoo wa mu lọwọ lọ si ibi ti O yan fun wọn lati fi ra ohun yowu ti o ba wu wọn lati jẹ ati lati fi ṣe ajọyọ pẹlu awọn ẹbi wọn ati awọn iransẹ ati awọn ẹru wọn ati awọn ọmọ Lefi ati awọn talaka niwaju Ọlọrun.
Lotitọ, awọn nkan ti a n so nibiyi le ṣe ajoji si ọpọ ti ko gbọ wọn ri. Amọ nkan ti a sọ fun wa ninu bibeli ni eyi. Ki wa ni idi ti Ọlọrun fi fẹ ki wọn ma jẹ idamẹwaa wọn niwaju rẹ? A ko tọka si eyi fun wa ninu bibeli. A kan ṣa sọ fun wa pe Ọlọrun fẹ ki awọn ọmọ Isiraẹli ma fi idamẹwaa wọn ṣe ipade ajọyọ lọdọọdun niwaju Oun ni. Ọdun kẹta nikan ni o jẹ wipe idamẹwaa ti wọn ba kojọ yoo lọ si ọdọ awọ ọmọ Lefi. Eyi ni a ṣe pe ọdun kẹta ni ỌDUN IDAMẸWAA. Awọn ti o ba si pa aṣẹ yi mọ ni ọdun kẹta ni anfaani lati fi igbọran wọn gbadura si Ọlọrun lati bukun fun wọn.
Àpẹrẹ ìgbọ́ràn àti àìgbọ́ràn sí òfin ìdámẹ́wàá
Ṣe awọn ọmọ Isiraẹli wa gbọran si aṣẹ Ọlọrun lori idamẹwaa? Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ko ki i ṣe gbogbo igba naa ni wọn gbọran si aṣẹ rẹ lori idamẹwaa, iyẹn gẹgẹ bi orilẹ-ede, paapaa-julọ niti ọdun idamẹwaa. Eyi si pa wọn lara lọna ti o ga ju ọgbọn ati oye wọn lọ. Amọ ṣa o, a ri apẹrẹ igbọran wọn ni asiko Ọba Hẹsikaya. Ọba yi gbe igbesẹ ti o tọna lati ri wipe awọn eniyan Juda gbọran si aṣẹ Ọlọrun lati mu gbogbo idamẹwaa ti o tọ si awọn ọmọ Lefi ati awọn alufaa wa fun wọn ni asiko tirẹ. Iwọ naa wo awọn nkan ti a kọ silẹ fun wa ninu bibeli lori eyi:
“Pẹlupẹlu, o pasẹ fun awọn eniyan ti n gbe Jerusalẹmu lati fi ipin awọn alufaa ati awọn ọmọ Lefi, fun wọn ki wọn ki o le di ofin Oluwa mu ṣinṣin. Bi aṣẹ naa ti jade, awọn ọmọ Isiraẹli mu ọpọlọpọ akọso ọka waini ati ororo, oyin wa, ati ninu gbogbo ibisi oko; ati idamẹwaa ohun gbogbo ni wọn mu wa ni ọpọlọpọ. Awọn ọmọ Isiraẹli ati Juda, ti n gbe inu ilu Juda wọn-ọn-ni, awọn pẹlu mu idamẹwaa maalu ati aguntan wa ati idamẹwaa gbogbo ohun mimọ ti a ya si mimọ fun Oluwa Ọlọrun wọn. Wọn si ko wọn jọ ni okiti okiti. Ni oṣu kẹta, wọn bẹrẹ sii ko wọn jọ ni okiti wọn si pari rẹ ni oṣu keje. Nigba ti Hesekaya ati awọn ijoye de, ti wọn si ri okiti wọn-ọn-ni, wọn fi ibukun fun Oluwa ati Isiraẹli eniyan rẹ. Hesekaya si beere lọdọ awọn alufaa ati awọn ọmọ Lefi ni ti okiti wọn-ọn-ni. Asaraya, olori alufaa, ti ile Sadoku, si da a lohun, o si wi pe, Lati igba ti awọn eniyan bẹrẹ sii mu ọrẹ wa sinu ile Oluwa, awa ni to lati jẹ, o si tun ku pupọ silẹ: Oluwa ṣaa ti bukun awọn eniyan rẹ; eyi ti o ku si ni iṣura nla yii.” (2Kíróníkà 31:4-10)
Bi a ti ṣe ri nibiyi, nitori aṣẹ Ọba Hẹsikaya ni awọn eniyan ṣe mura lati mu gbogbo idamẹwa ti o tọ si awọn ọmọ Lefi ati awọn alufaa Ọlọrun ti o wa ni aarin wọn wa. A si ri wipe nigba ti wọn ṣe eyi, olori alufaa gan-an le jẹri si pe ounjẹ pọ jaburata fun gbogbo awọn ọmọ Lefi ati awọn alufaa yoku. Eyi ṣi jẹ ki ọba ati awọn ijoye rẹ fi ogo fun Ọlọrun ti O fi si ọkan awọn eniyan rẹ lati ṣe ifẹ rẹ. Amọ ka sọ wipe ọba yi ko pa a laṣẹ nkọ? O ṣeeṣee ki awọn eniyan ilẹ naa tẹsiwaju lati ma kọ iha kokanmi si ofin Ọlọrun lori idamẹwaa sisan. Eyi yoo si jẹ ki wọn tẹsiwaju lati ma ri idajọ Ọlọrun lori aigbọran wọn.
Bi a tun ti ṣe ri ninu bibeli, ni gbogbo asiko ti awọn ọmọ Isiraẹli ko fi pa ofin Ọlọrun lori idamẹwaa mọ ni idajọ rẹ n wa sori wọn. Lọna wo? Fun apẹrẹ, ni asiko wolii Malaki, Ọlọrun sọ eyi fun awọn eniyan Juda lori aigbọran wọn si ofin idamẹwaa:
“Eniyan yoo haa ja Ọlọrun ni ole bi? Ṣugbọn ẹyin ṣa ti ja mi ni ole. Ṣugbọn ẹyin wi pe, Nipa bawo ni awa ja ọ ni ole? Nipa idamẹwaa ati ọrẹ. Rire ni a o fi yin rẹ: nitori ẹyin ti ja mi ni ole, ani gbogbo orilẹ-ede yii. Ẹ mu gbogbo idamẹwaa wa si ile iṣura mi, ki ounjẹ baa le wa ni ile mi, ẹ si fi eyi dan mi wo nisinsinyi ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, bi emi ki yoo ba ṣi awọn ferese ọrun fun yin, ki n si tu ibukun jade fun yin, to bẹẹ ti ki yoo si aye to lati gba a. Emi o si ba ajẹnirun wi nitori yin, oun ki yoo si run eso ilẹ yin, bẹẹ ni ajara yin ki yoo rẹ danu ninu oko, ni Oluwa awọn ọmọ ogun wi. Gbogbo orilẹ-ede ni yoo si pe yin ni alabukun-fun nitori ẹyin ti jẹ ilẹ ti o wu ni, ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.” (Málákì 3:8-12)
Awọn wo ni Ọlọrun fi ẹsun ole-jija kan nibiyi? Ṣe gbogbo orilẹ-ede ni? Rara o! Kiki orilẹ-ede Juda ni Ọlọrun fi ẹsun yi kan. Idi si ni pe awọn nikan ni orilẹ-ede ti O fun ni ofin idamẹwaa. Bi a si ti ṣe ri, ẹsun lori aigbọran si ofin idamẹwaa ni O fi n kan wọn ninu awọn ẹsẹ bibeli yi. O n jẹ ki o ye wọn pe Oun gangan ni wọn n ja lole nipa kikọ lati mu gbogbo idamẹwaa ti o tọ si awọn ọmọ Lefi ati awọn alufaa wọn wa, iyẹn ni gbogbo awọn ọdun idamẹwa. Eyi lo si fa a ti oniruuru ajẹnirun ṣe n ba wọn finra, ti ojo ko rọ bi o ti ṣe yẹ ki o ma rọ, ti oniruuru adanu si n ba iṣẹ ọwọ wọn. O wa ṣeleri fun wọn pe ti wọn ba le ronupiwada, Oun yoo ba ajẹnirun wi fun wọn ati wipe Oun yoo ri wipe wọn pada di alabukunfun ni aarin gbogbo orilẹ-ede yoku.
Ju gbogbo rẹ lọ, nkan ti a n sọ naa ni wipe ofin idamẹwaa ti o wa ninu iwe Ofin Mose wa fun awọn ọmọ Isiraẹli nikan. A ko fi fun gbogbo eniyan. Nitorina, egun ti Ọlọrun sọ wipe o wa lori awọn ọmọ Isiraẹli fun bi wọn ko ṣe pa ofin idamẹwaa mọ ko si lori gbogbo eniyan. Njẹ eyi wa tunmọ si pe ko tọna ki awọn ti ko ki i ṣe ọmọ Isiraẹli lati ma san idamẹwa? Rara o! O tọna. O tọna nitoripe bi a ti ṣe sọ siwaju, awọn eniyan ti n fun Ọlọrun ni idamẹwaa ki a to fun awọn ọmọ Isiraẹli ni Ofin Mose. Amọ wọn ko fun un ni awọn idamẹwaa yi nitoripe a pa a lasẹ fun wọn. Dipo bẹẹ, wọn fun un nitoripe a fun wọn ni oye lati ṣe bẹẹ nipa ifihan, o si tun wa lati inu ọkan wọn lati ṣe bẹẹ. Ọna ti wọn gba ṣe e ati awọn nkan ti o sọrọ mọ bi wọn ṣe gba ṣe e nikan naa ni o yatọ.
ÌDÁMẸ́WÀÁ LÁBẸ́ MÁJẸ̀MÚ TITUN
Bawo wa ni ti idamẹwaa labẹ majẹmu titun, iyẹn laarin awọn onigbagbọ ninu Jesu Kirisiti? Iha wo ni o yẹ ki wọn kọ si? Ti a ba wo oniruuru ijọ Ọlọrun loni, a o ri wipe oniruuru iha ni wọn kọ si ọrọ lori idamẹwaa. Awọn kan ka a si aṣẹ Ọlọrun fun gbogbo awọn Kirisitiẹni pẹlu. Nitorina, ni iwoye ti wọn, Kirisitiẹni yowu ti ko ba pa ofin idamẹwaa mọ naa wa ni abẹ egun, bi Ọlọrun ti ṣe sọ fun awọn Juu igba aye wolii Malaki. Bẹẹ si ni, a tun ri awọn ijọ miran ti wọn n sọ pe idamẹwaa ko kan ọmọ Ọlọrun. Ki ni idi? Ni iwoye ti awọn naa pẹlu, Jesu ti pa Ofin Mose ti o sọ idamẹwaa sisan di ọranyan rẹ. Nitorina, ko si nkan ti o kan ọmọ Ọlọrun kankan pẹlu a n san idamẹwaa.
Ewo wa ni iha ti o tọ ki a kọ si ọrọ idamẹwaa ninu awọn iha mejeeji yi? Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ko si eyi ti o tọ ninu iha mejeeji. Lakọkọ, bi a ti ṣe sọ siwaju, kiki orilẹ-ede Isiraẹli ni Ọlọrun fun ni ofin idamẹwaa, ko ki i ṣe gbogbo orilẹ-ede. Nitorina, ẹni ti ko ba ki i ṣe Juu ko si ni abẹ ofin idamẹwa, ko si si ẹnikẹni ti o gbọdọ mu ni tipatipa lati pa a mọ. Ọlọrun ko tilẹ ni ṣe idajọ ẹni naa lọna-kọna nipa Ofin Mose, ofin ti ko fun un. Wo nkan ti Pọọlu sọ lori eyi:
“Nitori Ọlọrun kii ṣe ojuṣaaju ẹnikẹni. Nitori iye awọn ti o ṣẹ ni ailofin, wọn o gba ijiya wọn gẹgẹ bi alailofin: ati iye awọn ti o ṣẹ labẹ ofin, awọn ni a o fi ofin da lẹjọ.” (Róòmù 2:11-12)
“Awa si nmọ pe ohunkohun ti ofin ba wi, o n wi i fun awọn ti o wa labẹ ofin, ki ẹnikẹni ma baa ni awawi kan, ati ki a le mu gbogbo araye wa sabẹ idajọ Ọlọrun.” (Róòmù 3:19)
Njẹ o ri bayẹn? Gbogbo nkan ti Ọlọrun pa a lasẹ fun awọn ọmọ Isiraẹli lori idamẹwaa ko kan awọn Keferi rara. Nitoriana, a ko le ba wọn ja tabi fi wọn re nitoripe wọn ko pa wọn mọ. Ọrọ nla!
Ẹkeji, Jesu ti fi opin si iṣẹ Ofin Mose nipasẹ iku rẹ nitootọ. Iṣẹ Ofin Mose wo ni O fi opin si? Iṣẹ Ofin Mose ti o fi iyapa si aarin awọn Juu ati awọn orilẹ-ede agbaye yoku ati iṣẹ Ofin Mose ti o n pe akiyesi eniyan si ẹṣẹ ṣugbọn ti ko ni agbara lati gba a lọwọ ẹṣẹ tabi lati sọ ọ di olododo niwaju Ọlọrun. Iwọ naa wo diẹ laara nkan ti a sọ nipa Ofin Mose ati nkan ti Jesu ṣe si i:
“Nitori naa ofin ti jẹ olukọni lati mu eniyan wa sọdọ Kirisiti, ki a le da wa lare nipa igbagbọ. Ṣugbọn lẹyin igba ti igbagbọ ti de, awa ko si labẹ olukọ mọ. Nitori pe ọmọ Ọlọrun ni ẹyin n ṣe, nipa igbagbọ ninu Kirisiti Jesu. Nitori pe iye ẹyin ti a ti batisi ninu Kirisiti, ti gbe Kirisiti wọ. Ko le si Juu tabi Heleni, ẹru tabi ominira, ọkunrin tabi obinrin: nitori pe, ọkan ni gbogbo yin jẹ ninu Kirisit Jesu.” (Gàlátíà 3:24-28)
“Nitori Kirisiti ni alaafia wa, ẹni ti o ti ṣe Juu ati Keferi ni ọkan, ti o si ti wo ogiri iṣodisi ti n bẹ laarin wa palẹ; O si ti fi opin si ọta naa ninu ara rẹ, ani ofin ati aṣẹ wọn-ọn-ni ti n bẹ ninu ilana; ki o le sọ awọn mejeeji di ẹni tuntun kan ninu ara rẹ, ki o si ṣe ilaja.” (Éfésù 2:14-15)
Njẹ o ri bayẹn? Yala Juu ni ọ ni tabi Keferi, niwọn igba ti o ba ti wa ninu Kirisiti Jesu, o ko si ni abẹ Ofin Mose mọ. Ko si ni dara ki o gbiyanju lati fi ara rẹ si abẹ rẹ. Nitoripe ko si anfaani kankan ti eyi yoo ṣe ọ. Idi si ni yi ti Kirisitẹni ko fi le tẹle Ofin Idamẹwaa ti a fifun awọn ọmọ Isiraẹli. Ko tilẹ ni itunmọ ki o tẹlẹ ofin naa. Nitoripe, yoo tunmọ si pe iwọ naa yoo ma jẹ idamẹwaa rẹ niwaju Ọlọrun fun odidi ọdun meji gbako. Yatọ si iyẹn, ibo ni o fẹ wa awọn ọmọ Lefi ati awọn alufaa iran Aaroni lọ lati ma ko idamẹwaa rẹ fun ni ọdun kẹta-kẹta?
Ṣe o wa ri idi bayi ti ko fi si aṣẹ kankan tabi ilana kankan ti a kọ silẹ lati ọdọ awọn apọsiteli igbaani lori idamẹwaa? Ko ki i ṣe wipe wọn ko mọ nipa idamẹwaa tabi wipe wọn gbagbe nipa rẹ. Oye rẹ ye wọn daradara. Amọ wọn ni imọ pe ko ki i ṣe aṣẹ fun awọn Kirisitiẹni lati ma a tẹlẹ.
Wayi o, pẹlu gbogbo nkan ti a sọ silẹ yi, njẹ ko fẹrẹ dabi ẹni pe ko yẹ ki Kirisitiẹni ma san idamẹwaa rara? Lotitọ, o fẹrẹ jọ bẹẹ. Amọ ko ki i ṣe bẹẹ. Ko ki i ṣe bẹẹ nitoripe bi a ti ṣe sọ siwaju, awọn eniyan ti n fun Ọlọrun ni idamẹwaa awọn nkan ti wọn ni ki a to fun awọn ọmọ Isiraẹli ni Ofin Mose. Ọlọrun si n tẹwọgba lọwọ wọn nitoripe wọn n fi fun un pẹlu igbagbọ ati ọkan ti o peye. Niwọn igba ti eyi si ribẹ, a jẹ wipe Ọlọrun ko tako ki a ma fun un ni idamẹwaa wa niyẹn. Amọ awa naa gbọdọ fifun un nigbakigba ti a ba n fifun un pẹlu igbagbọ wipe O lẹtọ si i. A si gbọdọ ṣe eyi pẹlu ọkan ti o peye.
Ta wa ni o yẹ ki a fun ni idamẹwaa wa, niwọn igba ti o jẹ wipe a ko ni nkankan ṣe pẹlu ofin idamẹwaa ti inu awọn Iwe Mose? Tani Jakọbu fun ni idamẹwaa tirẹ? A ko sọ fun wa. Tabi ṣe o jẹ idamẹwaa rẹ bi awọn ọmọ Isiraẹli ṣe ma n jẹ ti wọn ni? A ko sọ fun wa. Amọ a sọ fun wa ẹni ti Aburahamu fun ni idamẹwa tirẹ. Melkisedeki alufaa Ọlọrun Ọga-ogo ni o fun ni tirẹ. O tunmọ si pe iranṣẹ Ọlọrun ti Aburahamu bọwọ fun ni o tẹwọgba idamẹwaa rẹ.
Bi a si tun ṣe ri ni abẹ Ofin Mose, awọn iranṣẹ Ọlọrun naa ni a pa a laṣẹ pe ki awọn eniyan naa ma fun ni idamẹwa wọn ni ọdun kẹta-kẹta. Awọn iranṣẹ Ọlọrun yi ni yoo wa mọ bi wọn yoo ti ṣe jẹ ki o de ọdọ awọn opo, alaini-baba, alejo ati bẹẹbẹẹ lọ. Nitorina ti awa naa ba fẹ san idamẹwaa wa fun Ọlọrun, yoo mu ọgbọn wa fun wa lati fi fun awọn iranṣẹ Ọlọrun ti a yan le wa lori.
Ba wo wa ni ki a ṣe ma fun Ọlọrun ni idamẹwaa wa ni lemọlemọ si? Ko si ẹni ti o le kọ wa ni eyi? O ni i ṣe pẹlu ifihan Ọlọrun si ọkan wa ati bi oye rẹ ti ṣe mulẹ to ninu ọkan wa. Ẹ ranti pe ko ki i ṣe aṣẹ ni fifun Ọlọrun ni idamẹwaa jẹ fun wa. Dipo eyi, o jẹ nkan ti o gbọdọ wa lati ọkan wa lati ṣe, gẹgẹ bi o ti wa lati ọkan Aburahamu ati Jakọbu lati fun ni idamẹwaa awọn nkan wọn ni asiko kan. Amọ, bi a tun ti ti ṣe ri ninu bibeli, nigbati Aburahamu fun Ọlọrun ni idamẹwaa rẹ, alufaa Ọlọrun ti o gba ni ọwọ rẹ suure fun un. Nitorinaa, bi awa naa ba ṣe pongbẹ fun ire awọn iransẹ Ọlọrun wa si ni ki a ṣe ma fi idamẹwaa wa sọwọ́ si wọn ni lemọlemọ si.
ÌTỌ́JÚ ÀWỌN ÌRÁNṢẸ́ ỌLỌ́RUN LÁBẸ́ MÁJẸ̀MÚ TITUN
Nigba ti ọrọ wa ri bayi, ti o jẹ wipe idamẹwaa sisan ko ki i ṣe ofin fun awọn Kirisitiẹni, bawo ni ki wọn ṣe ma ṣe itọju awọn iranṣẹ Ọlọrun ti o wa lori wọn? Akọkọ naa, ti awa naa ba pinnu lati ma fi gbogbo idamẹwaa wa ṣọwọ si awọn ti o jẹ iranṣẹ Ọlọrun lori wa fun itọju wọn, ko lewọ rara. Ko ṣa ti wa lati ọkan wa lati ṣe bẹẹ ni o ṣe pataki ju.
Amọ, bi a ko tilẹ ṣe eyi, a ri wipe Kirisiti ti pa a laṣẹ fun wa lati ma ṣe ipinfunni ti o nitumọ pẹlu awọn ti o jẹ adari wa ninu ijọ, ti o n bọ wa pẹlu ọrọ rẹ. Iwọ naa wo diẹ lara aṣẹ ti a pa fun wa:
“Gẹgẹ bẹẹ ni Oluwa si ṣe ilana pe, awọn ti n waasu iyinrere ki wọn o si maa jẹ nipa iyinrere.” (1Kọ́ríntì 9:14)
“Ṣugbọn ki ẹni ti a n kọ ninu ọrọ naa maa ṣe alabaapin ohun rere gbogbo ti o ni fun ẹni ti n kọ ọ.” (Gàlátíà 6:6)
Njẹ o ri bayẹn? Yala a fun awọn iranṣẹ Ọlọrun ti o wa lori wa ni idamẹwaa wa tabi a ko fun wọn, ojuṣe wa ni lati ri wipe ebi ko pa wọn ati wipe awọn naa n ri ọwọ yọ. Ṣe a wa ri igbọran si eyi ninu bibeli bi? Bẹẹni, a ri igbọran si, gẹgẹ bi a tun ti ṣe ri aigbọran si.
Akọkọ naa, aigbọran si aṣẹ Oluwa yi ni o fa ọpọ nkan ti Pọọlu sọ fun awọn ara Kọrinti lori fififun awọn ti o n bọ wọn pẹlu ọrọ Ọlọrun (1Kọ́ríntì 9) Ko si ki wa ṣe kiki awọn ijọ Kọrinti nikan ni o kuna lori ọrọ yi. Ọpọlọpọ ijọ ti Pọọlu jẹ adari fun ni o kuna lori rẹ. Wo nkan ti o sọ fun awọn ara ijọ Filipi lori ọrọ yi i kanna:
“Ẹyin paapaa ṣa mọ pẹlu, ẹyin ara Filipi, pe ni ibẹrẹ iyinrere, nigba ti mo kuro ni Makedonia, ko si ijọ kan ti o fun mi ni iranlọwọ owo, bi ko ṣe ẹyin nikanṣoṣo. Nitori nigba ti mo wa ni Tẹsalonika, ẹyin ranṣẹ, ẹ si tun ranṣẹ lati pese fun aini mi.” (Fílípì 4:15-16)
Njẹ o ri bayẹn? Ni aarin gbogbo awọn ijọ awọn Keferi ti Pọọlu ti ṣiṣẹ iranṣẹ, ijọ Filipi nikan ni o mu aṣẹ Ọlọrun lati tọju awọn iranṣẹ Ọlọrun wọn ni asiko yi ṣẹ. Njẹ eyi wa bojumu bi? Ko bojumu rara. Eyi si wa lara awọn nkan ti o n ti awọn alufaa loni ti wọn fi n kan an ni tipatipa pe ki awọn Kirisitiẹni naa ma pa ofin idamẹwa ti a fun awọn ọmọ Isiraẹli mọ. Ẹru n ba wọn pe ti wọn ko ba ṣe eyi, o ṣeeṣe ki ebi lu awọn pa, ki awọn si ma ri ọwọ yọ, nigba ti awọn ọmọ ijọ wọn ba kọ lati pa aṣẹ Ọlọrun ti o sọ pe ki wọn ma tọju wọn mọ.
Sibẹsibẹ, ko si awawi fun iranṣẹ Ọlọrun kankan lati ṣi awọn ọmọ Ọlọrun lọna lori ọrọ idamẹwaa. Pọọlu ko wa awawi lati ṣi wọn lọna. Awọn apọsiteli yoku igbaani naa ko wa awawi lati ṣi awọn ọmọ Ọlọrun lọna lori ọrọ idamẹwaa. Dipo bẹẹ, nṣe ni wọn kọ wọn ni awọn nkan ti o yẹ ki o ye wọn lori ififuuni. Idi niyi ti wọn fi le yọ ọpọ awọn ọmọ Ọlọrun kuro ninu iṣẹ ni asiko yi. Wo diẹ lara nkan ti a sọ lori eyi:
“Awọn apọsiteli si n fi agbara nla jẹrii ajinde Jesu Oluwa; Ọlọrun si fun wọn ni oore-ọfẹ pupọ. Nitori ko si ẹnikan ninu wọn ti o ṣe alaini: nitori iye awọn ti o ni ilẹ tabi ile n ta wọn, wọn si mu owo ohun ti wọn ta wa. Wọn si mu wọn wa fun awọn apọsiteli, lati pin in fun olukuluku awọn ti o ṣe alaini, gẹgẹ bi aini wọn.” (Ìṣe Àpọ́sítélì 4:33-35)
Ki lo fa ti awọn apọsiteli fi fi agbara nla jẹrii ajinde Jesu Oluwa? Ara nkan ti o fa ni pe wọn ni anito ati aniṣẹku ohun gbogbo. Nitorina, wọn le pa ọkan pọ lati ṣe iṣẹ ti Ọlọrun gbe le wọn lọwọ. Ọpọ oniwaasu loni ni ko le pa ọkan pọ lati ṣe iṣẹ ti Ọlọrun gbe le wọn lọwọ. Ara idi si ni pe awọn ọmọ Ọlọrun ti wọn n ṣakoso ko mu itọju wọn ni pataki. Nitorina, wọn nilo lati sare-siwa ati ṣẹyin lati le mojuto ara wọn ati awọn ẹbi wọn. Ka wa lọ sọ wipe Pọọlu ni aya ati ọmọ nile ni, o ṣeeṣe ki oun naa ma le ṣe iṣẹ iranṣẹ rẹ bi o ti ṣe tọ ati yẹ pẹlu iha ti ọpọ ijọ kọ si itọju rẹ.
Ṣugbọn, a ri ninu awọn ẹṣẹ bibeli ti o wa loke yi pe ko ri bẹẹ rara nigba ti ijọ bẹrẹ. Awọn ọmọ Ọlọrun n mu nkan wa loorekoore fun awọn adari wọn ninu ijọ. Eyi si jẹ ki wọn le gbaju mọ iṣẹ iranṣẹ wọn. Yatọ si eyi, o tun jẹ ki wọn le tọju awọn alaini ti o wa ninu ijọ bi o ti ṣe yẹ. Ka wa lọ sọ wipe diẹ perete lara wọn ni o n mu nkan wa fun awọn iranṣẹ Ọlọrun wọn yi ni, ṣe wọn o le yọ awọn eniyan kuro ninu iṣẹ debi wipe ko ni si alaini kankan ni aarin wọn? Wọn ko ni le e ṣe bẹ.
Nitorina, yatọ si ti ojukokoro ọpọ adari ijọ loni, ara idi ti ijọ Ọlọrun ko ṣe ni agbara owó to lati yọ awọn ọmọ ijọ wọn kuro ninu iṣẹ ni pe ọpọ wa ya ahun si awọn adari wọnyi. Ṣe adari ijọ ti ko i ti ri ounjẹ jẹ tabi ti ko i ti ri owo ile-iwe awọn ọmọ rẹ san ni yoo ma a lepa lati yọ ẹnikẹni kuro ninu iṣẹ? Ohun ti eniyan ko ba ni, ko le fun ẹlomiran. Nitorina a nilo lati ronupiwada gidi lori ọrọ yi. Aijẹbẹ, bi o ti wu ki a mura si adura to, ọpọ ninu ijọ ni ko ni kuro ni ipo talika tabi akuṣẹ.
Ki ẹ si wa ma wo o, ko si ẹnikẹni ninu wa ti ko le pa aṣẹ Kirisiti lori ọrọ yi mọ o. Idi si ni pe ilana Ọlọrun ni pe ki gbogbo ifififunni wa wa ni ibamu pẹlu nkan ti a ni dipo nkan ti a ko ni. Idi niyi ti Jesu fi gboriyin fun opo talika kan ti o kan fi owo-idẹ wẹwẹ meji silẹ gẹgẹ bi ọrẹ lọjọ kan. Lotitọ, ọrẹ rẹ kere jọjọ loju awọn eniyan. Amọ ko kere rara loju Ọlọrun. Jesu tilẹ sọ wipe ọrẹ rẹ lo tobi julọ niwaju Ọlọrun ninu gbogbo ọrẹ ti awọn eniyan fi silẹ lọjọ naa. Ki lo faa? Nkan ti o fa a naa ni pe arabinrin yi fi ọrẹ rẹ silẹ ni ibamu pẹlu nkan ti o ni. Gbogbo nkan ti o ni lọwọ ni o tilẹ ko silẹ lọjọ naa. Nitori eyi, ti awa naa ba n fi tọkantọkan fifun awọn ti o jẹ iransẹ Ọlọrun le wa lori ni ibamu pẹlu bi a ti ṣe ni lọwọ si, Ọlọrun yoo tẹwọgba ọrẹ wa, bi awọn funra wọn gan ko tilẹ tẹwọgba.
(Wo: Lúùkù 21:1-2; 2Kọ́ríntì 8:12)
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Ju gbogbo rẹ lọ, nkan ti a fẹ ki o ye wa naa ni pe sisan idamẹwaa wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun, o si ma n fa ìre awọn iransẹ Ọlọrun sori eniyan. Amọ ko si ẹnikẹni ti o wa labẹ egun loni nitoripe ko ki i san idamẹwaa. Ṣugbọn ẹni ti o ba fẹ ki ibukun Ọlọrun ṣiṣẹ ninu aye oun lẹkunrẹrẹ, gbọdọ kọ lati ma pa aṣẹ rẹ mọ lori ififunni, paapaa-julọ si awọn iransẹ Ọlọrun, yala o n san idamẹwa tabi ko san an.
ÌBÉÈRÈ
– Bawo ni o ṣe ro wipe ẹkọ yi ṣe pataki to fun awọn ọmọ Ọlọrun?
Láti ọwọ́ Johnson O. Lawal
Copyright © 2024 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07025105978)
ÀKỌ́RÍ: ÀLÁ | ÀYỌKÀ: ÌṢE ÀPỌ́SÍTÉLÌ 2:17 | ỌJỌ́RÚ 11, ÒWEWÈ 2024
ÀKỌ́SÓRÍ: “…Daniẹli si ni oye iran ati ala ni oriṣiiriṣii.” (Dáníẹ́lì 1:17)
Ọ̀RỌ̀ ÌSÀÁJÚ
Ki ni a n pe ni ala? Iha wo ni o yẹ ki a kọ si ala, gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun? Ṣe bibeli tilẹ kọ wa ni ohunkohun lori iha ti o yẹ ki a kọ si ala? Awọn nkan wọnyi ni a fẹ gbeyẹwo ninu ẹkọ yi. A si fẹ gbe wọn yẹwo ki ma ba fi ara wa si abẹ ide ala ara wa tabi ti ẹnikẹni ati ki a ma ba padanu oye tabi itọni ti a le tipasẹ ala ni.
KÍ NI ÀLÁ?
Ala ni awọn iran iṣẹlẹ ti eniyan le ni ni oju-orun. Eyi tunmọ si pe asiko ti eniyan ba n sun ni eniyan ma n la ala. Lotitọ, eniyan le la ala ni asiko ti ko sun. Amọ irufẹ ala yi ni i ṣe pẹlu awọn nkan ti o wu wa pe ki wọn waye. Ti a ba si gbadura si Ọlọrun lori wọn, ti a si ṣiṣẹ tọ wọn, wọn yoo wa si imuṣẹ niwọn igba ti wọn ba ti wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun. Amọ ala ti a n sọrọ rẹ nibi ko ni nkankan ṣe pẹlu erongba tabi ete ọkan wọn. Dipo eyi, o ni i ṣe pẹlu awọn iran ti o tọ wa wa ni oju orun.
ÌSỌ̀RÍ ÀLÁ
Ipele meji pataki ni a le pin ala si. Akọkọ, a ni awọn ala ti o jẹ ifihan ninu ẹmi. Awọn wọnyi si ma n da lori aṣiri nkan ti o ti ṣẹlẹ ṣẹyin, aṣiri nkan ti o n ṣẹlẹ lọwọ tabi aṣiri nkan ti yoo ṣẹlẹ lọjọ iwaju. A si ni oniruuru ifarahan eyi ninu bibeli. Fun apẹrẹ, Josefu ọmọ Jakọbu la oniruuru ala gẹgẹ bi ọdọmọkunrin ti o fi aṣiri ọjọ-ọla rẹ han an. Awọn nkan wọnyi ṣi pada wa ṣẹ mọ lara, bi o tilẹ jẹ wipe o gba asiko diẹ. Lafikun, Solomọni la ala ni ọjọ kan ninu eyi ti Ọlọrun ti ni ki o bere ohun yowu ti o ba fẹ lọwọ Oun. O si bere fun ọgbọn ati oye lati ṣe idari awọn ọmọ Isiraẹli. Nigbati o si ji, o ri wipe ala ni. Amọ, awọn nkan ti o ri ni oju ala yi ṣẹ mọ lara. (Wo: (Jẹ́nẹ́sísì 37; 1Àwọn Ọba 3)
Isọri keji ala ni awọn ifihan iṣẹlẹ ti ko ni itumọ tabi ja mọ nkankan. Awọn ifihan wọnyi a ma waye nipasẹ ero-arotunro ati nipasẹ pe ọkan wa n gbiyanju laye ara rẹ lati ranti awọn ohun ti o ti ṣẹlẹ ṣẹyin. Ninu irufẹ awọn ala ba wọnyi ni awọn iṣẹlẹ ti ko ba baradọgba ti ma n sorapọ di ọkan. Solomọni tilẹ fun wa ni oye lori eyi nigba ti o sọ wipe: “Gẹgẹ bi ala ti n wa, nigba ti ilepa pupọ wa, bẹẹ ni ọrọ omugọ nigba ti ọrọ ba pọju.” (Oníwàásù 5:3) Ṣe o ri bayẹn? Ilepa ati ero ọkan wa le di nkan ti a o ma fi lala. Nitorina, irufẹ ala bi eyi ko ki i ṣe eyi ti eniyan gbọdọ mu ni pataki tabi ronu le lori.
ÌWÚLÒ ÀLA
Ki ni ala wa wulo fun? Bi a ti ṣe kọkọ sọ, ko ki i ṣe gbogbo ala naa ni a le ka si pataki. Awọn ala ti ko ni ori tabi idi ko ni iwulo kankan. Nitorina ko yẹ ki a fi asiko wa ṣofo le wọn lori. Amọ awọn ala ti o n fi nkan ẹmi han jẹ eyi ti o ṣe pataki ki a kiyesi, ki a ba a le mọ iwulo wọn. Ki si ni wọn wulo fun? Pataki lara wọn ni iwọnyi:
– Ìtọni: Ala le tọni sọna lori igbesẹ ti o yẹ ki o gbe lori awọn nkankan ti o fẹ ṣe tabi ti awọn miran fẹ ẹ ṣe. Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, lara awọn ọna ti Ọlọrun ma n gba tọ Ọba Sọọlu sọna ni ala wa. Ṣugbọn nigba ti o kuna, Ọlọrun ko ba sọrọ tabi tọ sọna nipasẹ ọna yi mọ. Bi a tun ṣe ri ninu bibeli, ọna kan gbogi ti Ọlọrun n gba tọ Josefu, ọkọ Maria iya Jesu, sọna ni ala. Nitorina a le gba itọsọna nipasẹ ala. (Wo: 1Sámúẹ́lì 28:6; Mátíù 1:18-25; Mátíù 2:9&19)
– Ìkìlọ̀: A tun ma n fun awọn eniyan ni ala lati kilọ fun wọn lori awọn nkan ti o n bọ wa ṣẹlẹ tabi lori awọn nkan ti o n ṣẹlẹ lọwọlọwọ, ki wọn ba a le mọ iru iha ti o yẹ ki wọn kọ si wọn. Fun apẹrẹ, a ri wipe nipasẹ ala ni a gba kilọ fun Josẹfu lori ewu ti o le wu Jesu gẹgẹ bi ọmọ-ọwọ lati ipasẹ ọba Hẹrọdu ati ọmọ rẹ ti o jọba rọpo rẹ (Mátíù 2:13-23). A si tun ri wipe a fi igba kan kilọ fun Ọba Nebukadinesari nipasẹ ala lori idajọ Ọlọrun ti o fẹ wa si ori rẹ (Dáníẹ́lì 4). Eyi n jẹ ki o ye wa pe a le gba ikilọ nipasẹ ala. (Wo: Jóòbù 33:14-18)
– Àṣírí: Ala tun jẹ ọkan lara awọn ọna ti a n gba tu aṣiri ninu ẹmi fun awọn eniyan. Bi a ti ṣe mẹnuba siwaju, nipasẹ ala ni a gba fi aṣiri ọjọ-ọla Josẹfu han an (Jẹ́nẹ́sísì 37:5-11). Nipasẹ ala ni a si tun gba fi aṣiri awọn ijọba aye yi ti yoo tẹle ijọba ọba Nebukadinesari han an (Dáníẹ́lì 2). Nitorina, nipasẹ ala a le gba aṣiri awọn nkan ti yoo ṣẹlẹ lọjọ ọla tabi eyi ti o ti ṣẹlẹ ṣẹyin tabi eyi ti o n ṣẹlẹ lọwọlọwọ.
ÀLÉÉBÙ ÀLA
Njẹ ala wa ni nkan ti a le pe ni aleebu bi? Bẹẹni, ala ni aleebu. Ọkan gbogi lara aleebu ala ni pe ko ki i ṣe gbogbo igba naa ni o ma n fun ni ifihan ti o peye to. Fun apẹrẹ, bi o tilẹ jẹ wipe awọn ala Josefu jẹ ki o ye wipe yoo di ẹni-nla ni ọjọ-ọla ati wipe yoo ga ju awọn arakunrin rẹ lọ, awọn ala wọnyi ko fi han pe yoo di ẹru tabi wipe inu tubu ni yoo gba di ẹni giga laye. Ti o ba wa lọ sọ ireti nu ni, paapaa julọ nigba ti gbogbo nkan dojuru fun, awọn ala rere yi ko ba ma ti wa si imuṣẹ.
Aleebu keji ti ala ni ni wipe ọpọ igba ni ko ki wa ni ọna ti oye itumọ rẹ yoo fi han kedere si wa. Fun apẹrẹ, ni ọjọ kan, awọn ijoye Farao meji kan ti Josefu ba pade ninu tubu la ala ọtọọtọ. Amọ ko si eyi ti o mọ itunmọ ala ti o la ninu wọn. Eyi si fi ibanujẹ sinu ọkan wọn. Ti ko ba wa si ẹni ti o le tunmọ ala naa fun wọn ni, wọn ko ba ma mọ iha ti o yẹ ki wọn kọ si. (Wo. Jẹ́nẹ́sísì 37&40)
Siwaju si, bi a ti ṣe ri ninu iwe Daniẹli, igba meji ọtọọtọ ni Ọba Nebukadinesari la ala ti ko mọ itumọ rẹ. Ti ko ba wa si ẹni ti o le tunmọ awọn ala naa fun ni, ko si bi oun tabi awa yoo ti ṣe le so imuṣẹ awọn ala naa mọ wọn. Eyi wa lara idi ti ọpọ fi ma n yọnu tabi banujẹ ti wọn ba ti la ala ti oye rẹ ko si ye wọn yekeyeke. (Wo: Dáníẹ́lì 2&4)
Aleebu kẹta ala ni pe ko ki i ṣe gbogbo eniyan ni a ma n ba sọrọ lemọ́-lemọ́ nipasẹ ala. Ọpọ loni ni o ma n wu wọn ki wọn ma la ala fun itọni, ikilọ tabi aṣiri.. Ṣugbọn ko ki i ṣe gbogbo eniyan Ọlọrun ma n ṣaba ba sọrọ nipasẹ ala. Lotitọ, gbogbo eniyan ni o ma n la oniruuru ala. Ko si si ẹni naa ti yoo sọ wipe oun ko la ala ti o ni itunmọ ri. Amọ, ti a ba n sọrọ nipa pe ki a ma fi ala ba eniyan sọrọ loore-koore, fun itọni, aṣiri tabi ikilọ, ko ki i ṣe gbogbo eniyan ni eyi ma n ṣẹlẹ si. Ẹni ti eyi ko ba si ki i ṣẹlẹ si gbọdọ sọ ara rẹ lati ma gbiyanju lati ru ala soke lọkan ara rẹ nipasẹ adura ati awẹ gbigba, ki o si ṣi ara rẹ lọna. Idi si ni pe ala ti o jẹ ifihan ẹmi ko ki i ṣe nkan ti a le mu wa si ojú-orun wa bi o ti ṣe wu wa. Ẹni ti Ọlọrun ko ba fẹ ba sọrọ nipasẹ ala, ko si ohun ti ẹni naa le ṣe ti Ọlọrun yoo fi ba sọrọ nipasẹ rẹ. A si ri apẹrẹ eyi ninu itan Ọba Ṣọọlu. Ni awọn ọjọ ikẹyin rẹ laye, o ṣafẹri ki Ọlọrun ti pasẹ ala ba a sọrọ. Ṣugbọn Ọlọrun ko da lohun rara. Nkan ti o si sun de ọdọ arabinrin oṣo kan ni eleyi. Awa naa wa gbọdọ ṣọ ara wa lori ki a fẹ fi tipa-tipa mu Ọlọrun lati ba wa sọrọ nipasẹ ala. Aijẹbẹ, awọn ẹmikẹmi le tipasẹ eyi bẹrẹ si ni fi alakala ba wa sọrọ. (Wo: 1Sámúẹ́lì 28)
Aleebu kẹrin ala ni pe ko ki i ṣe gbogbo ala ti o jẹ ifihan nipa ti ẹmi ni o n ti ọdọ Ọlọrun wa. Lotitọ, ọrọ Ọlọrun jẹ ki o ye wa pe awọn ti Ẹmi mimọ ba n gbe inu wọn le ma la ala, ki wọn ma ri ifihan lati ọdọ Ọlọrun ni oju-orun wọn. Fun apẹrẹ, Peteru, nigba ti o n ṣalaye fun awọn eniyan lori iriri ifidefọ wọn ni ọjọ Pẹntikọsiti, sọ wipe:
“’Ni ikẹyin ọjọ,’ Ọlọrun wi pe, ‘Emi yoo tu Ẹmi mi jade sara eniyan gbogbo, awọn ọmọ yin ọkunrin ati awọn ọmọ yin obinrin yoo maa sọtẹlẹ, awọn ọdọmọkunrin yin yoo si maa riran, awọn arugbo yin yoo si maa la ala.” (Ìṣe Àpọ́sítélì 2:17)
Njẹ o ri bayẹn? Ala lila wa lara ifarahan Ẹmi Ọlọrun ninu aye awọn eniyan. Nitorina, a le ma gbadura pe ki Ọlọrun mu ọrọ rẹ ṣe laarin gbogbo awọn ọmọ rẹ nipa fifun wa ni ala ti o wa ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ. Amọ ṣa o, Satani naa le mu ifihan wa fun awọn eniyan ni oju-orun wọn. Ẹni ti ko ba wa ni oye yi ṣeeṣe ki o tẹwọ gba ala ibi tabi ala ti yoo ṣi i lọna ni ọwọ rẹ, ki o si tipasẹ eyi bọ si abẹ ide rẹ.
Bawo ni a ṣe wa le ṣe idamọ ala ti o ti ọdọ Ọlọrun wa yatọ si eyi ti o ti ọdọ eṣu wa? Akọkọ, a le mọ eyi nipa ṣiṣe agbeyẹwo ala naa pẹlu nkan ti ọrọ Ọlọrun sọ nipa ifẹ rẹ fun wa. Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, Ọlọrun ba awọn wolii igba aye Jeremaya wijọ lori awọn ala ti wọn n la. O ṣi jẹ ki o ye awọn eniyan wipe wọn ko gbọdọ tẹwọ gba awọn ala wọnyi. Ki si ni idi? Idi ni pe awọn ala naa ko wa ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ ti o jẹyọ ninu ọrọ rẹ. Eyi ja si pe ala ti ko ba ti wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun fun wa, bi a ti ṣe fi han wa ninu bibeli, ko ti ọdọ Ọlọrun wa bi ko ṣe ọdọ eṣu. A si gbọdọ kọ ọ. (Wo: Jeremáyà 23:25-29)
Ekeji, ala ti ko ba ti wa lati fi ogo ati iyin fun Ọlọrun ko ki i ṣe lati ọdọ Ọlọrun. Ala ti o wa lati fi eniyan tabi eṣu tabi ẹda yowu ti o le jẹ si ipọ Ọlọrun ko ki i ṣe ti Ọlọrun bi ko ṣe ti eṣu. A si gbọdọ kọ ọ.
Ẹ̀BÙN ÌTUNMỌ̀ ÀLÁ
Bawo wa ni a ṣe le mọ itunmọ ala ti a la, ti a o fi le sọ boya itọni ni, ikilọ ni tabi aṣiri ni? Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ni aye igbaani ati labẹ ofin Mose, a ri awọn ti Ọlọrun fun ni ẹbun itunmọ ala. Fun apẹrẹ, Josefu ni ẹbun itunmọ ala. O si ma n jẹ ki o ye awọn eniyan pe Ọlọrun ni o fun oun ni ẹbun naa. Iwọ naa wo nkan ti o sọ fun awọn ijoye Farao ti wọn la ala, ti oye awọn ala naa ko si ye wọn: “Ọlọrun nikan ni o ni itumọ. Ẹ sọ awọn ala yin fun mi.” (Jẹ́nẹ́sísì 40:8) Tun wo nkan ti o sọ fun Farao nigba ti o fẹ tunmọ ala rẹ fun ọ: “Ki i ṣe agbara mi, ṣugbọn, Ọlọrun ni yoo fun Farao ni itumọ ala naa.” (Jẹ́nẹ́sísì 41:16)
Siwaju si, a ri wipe Daniẹli naa ni ẹbun itunmọ ala. Wo nkan ti bibeli sọ nipa rẹ: “…Daniẹli si ni oye iran ati ala ni oriṣiiriṣii.” (Dáníẹ́lì 1:17). Eyi jasi pe ọkunrin yi ni ẹbun itunmọ ala. Nibo ni o ti wa ri ẹbun yi? Ọlọrun ni o fi fun un. Bawo ni a ṣe mọ? A mọ nipa wipe nigba ti o fẹ tunmọ ala Ọba Nebukadinesari fun un, nkan ti ọ sọ ni eyi: “Ko si aworawọ kan, apogede, onidan tabi alafọṣẹ ti o le ṣe alaye aṣiri ti ọba beere fun ṣugbọn, Ọlọrun kan n bẹ ni ọrun ti o n fi aṣiri han…” (Dáníẹ́lì 4:27-28) Njẹ o ri bayẹn? Ọlọrun nikan ni Ọba ti o ma n fi aṣiri han eniyan. Nitorina, ti ko ba fun wa ni oye ala ti a ba la, a ko le ni oye rẹ.
Amọ ṣa o, njẹ Ọlọrun tun n fun awọn eniyan ni ẹbun itunmọ ala loni bi? Abi ki a sọ wipe ṣe itunmọ ala wa ni ara ẹbun ẹmi bi? Bi a ti ṣe sọ siwaju, ala lila wa lara awọn ọna ti Ẹmi Ọlọrun ma n gba fun awọn ọmọ Ọlọrun ni ikilọ, itọni tabi aṣiri ikọkọ nipa ohun ti o n ṣẹlẹ lọwọlọwọ, ohun ti o ti ṣẹlẹ ṣẹyin tabi ohun ti yoo pada wa ṣẹlẹ. Amọ ko si ibi ti a kọ si ninu bibeli pe ẹbun Ẹmi mimọ ni itunmọ ala jẹ fun awọn ọmọ Ọlọrun loni.
Bawo wa ni a ṣe le mọ itunmọ ala ti a ba la loni, niwọn igba ti ko si awọn ti a le tọka si gẹgẹ bi awọn ti o ni ẹbun itunmọ ala? Akọkọ, a le mọ itunmọ rẹ nipa gbigbadura si Ọlọrun fun oye ti o peye nipa ala naa, ki a ma ba a ṣi i tunmọ. A ri wipe Daniẹli ati awọn akẹgbẹ rẹ gbadura si Ọlọrun lati le mọ itunmọ ala ọba Nebukadinesari. Ọlọrun si da wọn lohun. Amọ ki lo fa ti wọn ṣe gbadura fun itunmọ rẹ? Idi ni wipe ẹmi wọn ti fẹ lọ si. Ka sọ wipe ọba yi ko mu ọrọ ala naa ni pataki debi wipe o ṣetan lati gba ẹmi awọn amoye Babiloni ni, wọn ko ba ma ti ka ala rẹ si rara. Nikukuru, ti ala kan ba ru wa loju tabii ti oye itunmọ rẹ ko ye wa, nṣe ni ki a ba Ọlọrun sọrọ lori oye ala naa, ki a ma ba a ṣi i tunmọ. Niwọn igba ti Ẹmi Ọlọrun si wa ninu wa lati dari wa sinu gbogbo otitọ ati lati fi aṣiri awọn nkan ti o n bọ han wa, o didan ki Ọlọrun da wa lohun. (Wo: Dáníẹ́lì 2:17-24; Jòhánù 16:13)
Ọna keji ti a le gba mọ itunmọ ala ni ki a ṣe agbeyẹwo rẹ pẹlu ọrọ Ọlọrun. O tilẹ jẹ dandan fun wa lati ṣe agbeyẹwo ala yowu ti a ba la pẹlu ọrọ Ọlọrun. Aijẹbẹ, a le gbe nkan gbagi, ki a si bẹrẹ si ni wuwa lodi si ifẹ Ọlọrun. Fun apẹrẹ, ọpọ ni o ti ṣi ọkọ tabi aya fẹ nitoripe wọn ko wo bi ala ti wọn la ṣe wa ni ibamu pẹlu ọrọ Ọlọrun si. Ọrọ Ọlọrun ti o wa ninu Iwe mimọ nikan ni o peye lati tọni ati lati ma ṣi ni dari, niwọn igba ti a ko ba ti ṣi i tunmọ. Iwọ naa wo nkan ti bibeli sọ nipa ara rẹ:
“Gbogbo Iwe-mimọ ni o ni imisi Ọlọrun ti o si ni ere fun ẹkọ, fun ibaniwi, fun itọni, fun ikọni ti o wa ninu ododo. Ki eniyan Ọlọrun le pe, ti a ti mura silẹ patapata fun iṣẹ rere gbogbo.” (2Tímótì 3:16-17)
Njẹ o ri bayẹn? Ọrọ Ọlọrun ti o wa ninu Iwe-mimọ nikan ni o le sọ wa di pipe ni gbogbo ọna, ti ko si ni ṣi wa lọna. Nitorina, ala yowu ti a ba la gbọdọ wa ni ibamu pẹlu nkan ti a sọ ninu ọrọ Ọlọrun. Aijẹbẹ, ko ti ọdọ Ọlọrun wa, bi mo ti ṣe sọ tẹlẹ. A si gbọdọ gbe sọnu.
ÌMÚṢẸ ÀLÁ
Ki a tilẹ wa sọ wipe ala ti a la wa lati ọdọ Ọlọrun, ṣe dandan ni ki o wa si imuṣẹ? Bi a ti ṣe sọ siwaju, ko ki i ṣe gbogbo ala naa ni o jẹ aṣiri ikọkọ. Awọn ala kan wa fun itọni. Awọn miran si wa fun ikilọ. Ti a ba si gba itọni tabi ikilọ ti a ti ipasẹ ala fun wa gbọ, ti a si ṣiṣẹ le lori, o di dandan ki a di pipamọ kuro ninu ewu tabi ki a jẹ alabukunfun ni ibamu pẹlu ala naa.
Amọ ti a ba n sọrọ nipa ala ti o ni i ṣe pẹlu aṣiri nkan ti yoo ṣẹlẹ, imuṣẹ rẹ da lori iha ti ẹni ti ọrọ kan ba kọ si i. Ki a ma gbagbe pe eṣu naa le fun yan ni ala lori awọn nkan ti o n gbero lati ṣe si ẹni naa tabi lati ṣi ẹni naa lọna. Iha ti ẹni naa ba si wa kọ si ala naa ni yoo sọ boya yoo wa si imuṣẹ tabi ko ni wa si imuṣẹ.
Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, Josefu la oniruuru ala ti o n fi aṣiri ọjọ-ọla rẹ han an. Ọlọrun lo si fun ni awọn ala yi. Ṣe wọn wa wa si imuṣẹ tabi wọn ko wa si imuṣẹ? Wọn wa si imuṣẹ? Ki ni o jẹ ki wọn wa si imuṣẹ? Akọkọ, igbagbọ Josẹfu ninu agbara Ọlọrun lati mu awọn ala rere rẹ ṣẹ wa lara idi ti wọn ṣe wa si imuṣẹ. Ka lọ sọ wipe ko gba pe Ọlọrun le mu awọn ala naa wa si imuṣẹ ni, o ṣeeṣe ki o ma gbe igbe aye ẹni ti o n lepa lati di giga.
Ekeji, ifarada Josẹfu ran imuṣẹ ala rere rẹ lọwọ. Bi o tilẹ jẹ wipe Josẹfu dojukọ oniruuru iṣoro ti o pada sọ di ero inu tubu, o farada ohun gbogbo ti o ba pade. Ko gba ẹmi ara rẹ tabi ki o darapọ mọ ẹgbẹ buburu. Idi si ni pe o mọ lọkan rẹ pe Ọlọrun ti O fun oun ni awọn ala rere ti o n la ko ni ṣe alai mu awọn ala naa ṣẹ.
Ẹkẹta, Josẹfu jẹ ẹnikan ti o jafafa lẹnu iṣẹ. Ko kan joko-kalẹ tẹtẹrẹ, ki o si ma reti ki Ọlọrun sọ di ẹni giga. Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ni asiko ti o wa ni ile Potifa gẹgẹ bi ẹru ati ni asiko ti o wa ninu tubu gẹgẹ bi ẹlẹwọn ko fi iṣẹ yowu ti wọn ba fun falẹ rara. Idi si ni yi ti o fi jẹgbadun ojurere igbega lọdọ Pọtifa ati Olori-ẹṣọ inu tubu. Nigbati o si tun ni anfaani lati ba Farao sọrọ, isọrọ si rẹ fi han gẹgẹ bi ọlọpọlọ pipe ti o le ṣakoso orilẹ-ede. Ka lọ sọ wipe o fi ara rẹ jin fun igbe aye ọlẹ tabi imẹlẹ ni, ko ba ma ti ja mọ nkankan laye, bi o tilẹ jẹ wipe a ti fi han ninu ala pe yoo di ẹni giga. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 39)
Ẹkẹrin, Josẹfu fi ara rẹ jin fun igbe aye iwa-mimọ ati ikora-ẹni-nijanu. Bi o tilẹ jẹ wipe o ni anfaani lati ba aya oluwa rẹ, Potifa, sun, Josẹfu kọ lati ba obinrin naa da nkan pọ, ki o si ṣẹ si Ọlọrun. Lotitọ, eyi jẹ ki o di ero inu tubu. Amọ nitoripe o bọwọ fun Ọlọrun ati fun oluwa rẹ, ni asiko ti o yẹ, Ọlọrun da a lare. Nitorina, ki a la ala rere si ara wa ko to. Ti a ko ba gbe igbe aye ti o wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun, o ṣeeṣe ki ete rere Ọlọrun ma wa si imuṣẹ lori aye wa.
Nibakanna, ẹniyan le la ala ibi tabi ala ti o n fi idajọ Ọlọrun ti o n bọ han. Ti ẹni naa ko ba gbe igbesẹ ironupiwada, ala naa yoo pada wa si imuṣẹ lori rẹ, ti a ko ba ṣaanu fun. Fun apẹẹrẹ, ọba Nebukadnesari la ala lọjọ kan ti o ni i ṣe pẹlu idajọ Ọlọrun ti o n bọ wa sori rẹ. Daniẹli ni ẹni naa ti o sọ itunmọ ala naa fun un. O si kilọ fun ni ọjọ ti a n wi yi pe ki o ronupiwada, ki a ala ibi ma ba a ṣẹ le lori. O wa ṣeeṣe pe ọba yi i ronupiwada fun sáà diẹ. Ṣugbọn a ri wipe lẹyin ọdun kan gerege ti o ti la ala yi, ala naa pada ṣe mọ lara. Ki si ni idi? Idi naa ni pe ironupiwada rẹ ko peye, ki a tilẹ sọ wipe o ronupiwada. (Wo: Dáníẹ́lì 4)
Nitorina, boya ala wa yoo wa si imuṣẹ tabi ko ni wa si imuṣẹ ku si ọwọ wa. Ti a ba gbe igbesẹ ti o tọ, ni ibamu pẹlu awọn nkan ti Ọlọrun fi han wa, ala wa ti o n fi ete rere rẹ han si wa di dandan ki o wa si imuṣẹ, bẹẹ si ni ala ti o n fi idajọ rẹ tabi ibi ti o fẹ ṣelẹ waye han wa ko ni wa si imuṣẹ le wa lori. Amọ ti a ko ba gbe igbesẹ ti o wa ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ, ifihan ti a rigba lati ipasẹ ala wa ko ni pada lere lori fun wa.
Bawo wa ni ti ala ti Satani n fun wa lati dẹruba wa tabi lati ṣi wa lọna? Bi mo ti ṣe sọ siwaju, a gbọdọ gbe ala yowu ti a ba la wo pẹlu ọrọ Ọlọrun lati le mọ ibi ti o ti ṣẹ wa. Ti a ba si ri wipe ọdọ eṣu ni ala naa ti ṣẹ wa, a gbọdọ duro sori nkan ti ọrọ Ọlọrun sọ tako ifẹ esu ni. Ni afikun, a gbọdọ kun fun adura ati ijẹwọ ọrọ Ọlọrun lati yi ibi yowu ti eṣu n gbero lodi si wa danu.
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Ala jẹ ọkan lara awọn ọna ti Ọlọrun ma n gba ba awọn eniyan sọrọ. Amọ ko ki i ṣe Ọlọrun nikan ni O le ba wa sọrọ lati ipasẹ ala – Satani naa le ba wa sọrọ lati ipasẹ rẹ. Yatọ si iyẹn, ala ti o sorọ mọ ero ọkan wa tabi awọn iṣẹlẹ ti a ti la kọja le waye. Idi si ni yi ti a fi nilo lati mọ ifẹ Ọlọrun fun wa, bi a ti ṣe la a kalẹ ninu ọrọ rẹ, ki a ma ba ti ipasẹ ala ṣi wa lọna ati ki a le mọ irufẹ iha ti o yẹ ki a kọ si ala yowu ti a ba la.
ÌBÉÈRÈ
– Njẹ o ro wipe irufẹ ẹkọ yi wulo fun awọn ọmọ Ọlọrun bi?
– Bawo ni ẹkọ yi ṣe ṣe ọ ni anfaani si?
Lati ọwọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2024 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07025105978)
ÀKỌ́RÍ: MÁ YA Ọ̀LẸ | ÀYỌKÀ: MÁTÍÙ 25:14-30 | ỌJỌ́RÚ 24, AGẸMỌ 2024
ÀKỌ́SÓRÍ: “Ni ti iṣẹ ṣiṣe, ẹ ma ṣe ọlẹ; ẹ ma fi itara sin Oluwa.” (Róòmù 12:11)
Ọ̀RỌ̀ ÌSÀÁJÚ
Ara awọn nkan ti a jẹ ki o ye wa ninu bibeli ni pe ọmọ Ọlọrun ko gbọdọ ya ọlẹ ni ọnakọna. Aijẹbẹ, yoo mu abuku tabi ẹgan ba iyinrere Jesu. Idi si niyi ti a fi gbọdọ ma pe akiyesi awọn ọmọ Ọlọrun ninu awọn ijọ wa si ohun ti o n jẹ iwa ọlẹ, iwa imẹlẹ ati iwa ilọra ati oniruuru ọna ti wọn le gba farahan ninu aye wa, ki a ba a le yago fun wọn. Nitorina, ninu ẹkọ yi, a o ṣe agbeyẹwo nkan ti ọrọ Ọlọrun sọ lori gbigbe igbe aye ọlẹ, awọn ọna ti iwa ọlẹ ma n gba farahan ati ewu ti o sọrọ mọ igbe aye ọlẹ. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun fun wa ni oye nkan wọnyi ni ọna ti o peye, ki O si tun fun wa ni okun lati ṣe amulo wọn. Amin.
TANI Ọ̀LẸ?
Ti a ba pe eniyan ni ọlẹ, a n sọrọ nipa ẹni ti ko ṣetan lati ṣe awọn nkan ti o tọna fun lati ṣe ni asiko ti o yẹ ki o ṣe wọn, ki o ba le mojuto ohun gbogbo ti o jẹ ojuṣe rẹ. Fun apẹrẹ, Jesu pa owe kan ti o fun wa ni apẹrẹ nkan ti o tunmọ si lati jẹ ọlẹ. Iwọ naa wo bi owe naa ti ṣe lọ:
“A si tun fi ijọba ọrun we ọkunrin kan ti o n lọ si irin-ajo. O pe awọn ọmọ-ọdọ rẹ, o si ko ohun ni rẹ fun wọn. O fun ọkan ni talẹnti marun-un, o fun ekeji ni talẹnti meji, o si fun ẹkẹta ni talẹnti kan, o fun olukuluku gẹgẹ bi agbara rẹ ti mọ, o si lọ irin-ajo tirẹ. Ọkunrin ti o gba talẹnti marun-un bẹrẹ lẹsẹkẹsẹ lati fi owo naa ṣowo. Laipẹ, o si jere marun-un miiran. Ọkunrin ti o gba talẹnti meji naa fi tirẹ ṣowo. Laipẹ, o si jere talẹnti meji miiran. Ṣugbọn ọkunrin ti o gba talẹnti kan, o wa iho ni ilẹ, o si bo owo ọga mọ ibẹ. Lẹyin ọjọ pipẹ, oluwa awọn ọmọ-ọdọ de lati ajo rẹ. O pe wọn jọ lati ba wọn ṣiro owo rẹ. Ọkunrin ti o gba talẹnti marun-un, mu marun-un miiran pada wa, o wi pe, ‘Oluwa, iwọ ti fi talẹnti marun-un fun mi, mo si ti jere marun-un miiran pẹlu rẹ.’ Oluwa rẹ wi fun un pe, ‘O ṣeun iwọ ọmọ-ọdọ rere ati oloootọ: iwọ ṣe oloootọ ninu ohun diẹ, emi yoo fi ọ se olori ohun pupọ, bọ sinu ayọ oluwa rẹ.’ Eyi ti o gba talẹnti meji wi pe, ‘Oluwa, iwọ fun mi ni talẹnti meji lati lo, emi si ti jere meji miiran.’ Oluwa rẹ si wi fun un pe ‘O ṣeun, iwọ ọmọ-ọdọ rere ati oloootọ. Iwọ ti jẹ oloootọ ninu ohun diẹ, emi yoo fi ọ ṣe olori ohun pupọ. Iwọ bọ sinu ayọ oluwa rẹ.’ Nikẹyin, ọkunrin ti a fun ni talẹnti kan wa, o wi pe ‘Oluwa, mo mọ pe onroro eniyan ni iwọ n ṣe iwọ n kore nibi ti iwọ ko gbin si, iwọ n ko jọ nibi ti iwọ ko o ka si. Emi bẹru, mo si lọ pa talẹnti rẹ mọ sinu ilẹ. Wo o, nnkan rẹ niyii.’ Ṣugbọn oluwa rẹ dahun pe, ‘Iwọ ọmọ-ọdọ buburu ati onilọra, iwọ mo pe emi n kore nibi ti emi ko funrungbin si, emi si n ko jọ nibi ti emi ko o ka si. Nigba naa iwọ iba kuku fi owo mi si ile ifowopamọ ti emi ba de emi iba le gba owo mi pẹlu ere. O si pasẹ ki a gba talẹnti naa lọwọ rẹ, ki a si fun ọkunrin ti o ni talẹnti mẹwaa. Nitori ẹnikẹni ti o ba ni a o fun si i, yoo si tun ni si lọpọlọpọ. Ṣugbọn lati ọwọ ẹni ti ko ni ni a o ti gba eyi ti o ni. Nitori idi eyi, gbe alailere ọmọ-ọdọ ju u sinu okunkun lode, ibẹ ni ẹkun oun ipayinkeke yoo gbe wa.’” (Mátíù 25:14-30)
Ki ni owe yi da le lori? O da lori ọkunrin kan ti o fun awọn iranṣẹ rẹ ni talẹnti melokan lati ṣiṣẹ. Wayi o, talẹnti ni asiko ti a n sọ yi ko ni nkankan ṣe pẹlu amuyẹ ti eniyan ni; dipo eyi, o ni i ṣe pẹlu owo. Awọn onimọ ijinlẹ tilẹ jẹ ki o ye wa pe ọpọlọpọ owo ni talẹnti kan ni asiko yi. Ki lo wa fa ti ọkunrin yi ṣe ko talẹnti rẹ le awọn ọmọ-ọdọ rẹ lọwọ. Akọkọ, o ko o le wọn lọwọ nitoripe o fẹ rin irinajo. Ekeji, o ko o le wọn lọwọ nitoripe ko fẹ ki owo naa kan ma gbelẹ ni asiko ti ko ni si nile – o fẹ ki owo naa di pupọ si. Ẹkẹta, ko fẹ ki awọn ọmọ-ọdọ yi kan joko silẹ ki wọn ma jẹ ounjẹ rẹ ati ki wọn ma mu omi rẹ, ki wọn si tun ma gbe ile ọfẹ, lalai ṣiṣẹ tọ awọn nkan wọnyi.
Eyi n fi han wa pe Ọlọrun ti O da wa ko fẹ ki awọn nkan ti O ko fun wa tabi fi si arọwọto wa ma pẹdin tabi bajẹ mọ wa lọwọ, ṣugbọn O fẹ ki wọn ma pọ si, ki wọn si tun ma dara si ni ọwọ wa. Ọna wo wa ni eyi yoo gba sẹlẹ? Ọkan pataki lara ọna ti eyi yoo gba ṣẹlẹ ni ki a bẹrẹ si ni ṣiṣẹ pẹlu ati lori ohunkohun ti Ọlọrun ba ko le wa lọwọ. Idi si ni yi ti O ṣe ṣeto ọgba ajara kan ni Edẹni ni atetekọṣe fun Adamu, ọkunrin akọkọ, lati ma ṣiṣẹ ninu rẹ. Bi o tilẹ jẹ wipe ohun gbogbo ti Adamu nilo lati gbe ile aye pẹlu irọrun ni a ti pese ki a to da a, Ọlọrun fi sinu ọgba ajara ti o da yi lati kọ ọ ni bi a ti ṣe n ṣiṣẹ tọ nkan ti a ni, ki o ba le gberu ati dara si ni ọwọ wa. Aijẹbẹ, aye yoo kan wa loju kanna ni. Yatọ si eyi, ọpọlọ ti Ọlọrun fun eniyan gan yoo tun jọba, ko ni ji pepe rara. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 2:8-15)
Nkan ti a n sọ, ni kukuru, ni pe ọna pataki kan lati sọ awọn nkan ti Ọlọrun fun wa di pupọ si ati lati sọ ọpọlọ ati awọn amuyẹ ti Ọlọrun fun wa ji, ki wọn ba a le ma ṣiṣẹ de ibi ti o lapẹrẹ, ni ki a fi wọn ṣiṣẹ. Nkan ti ọkunrin olowo ti Jesu si n sọrọ nipa rẹ si ṣe ni eyi pẹlu awọn ọmọ-ọdọ rẹ. A si wa ri wipe, o ko owo fun ẹnikọọkan wọn ni ibamu pẹlu agbara tabi amuyẹ rẹ. Eyi n jẹ ki o ye wa pe ko si ẹni ti ko le ṣiṣẹ, niwọn igba ti ẹni naa ko si ni ori-idubulẹ aisan ti ko le jẹ ki o roju-raye ṣe ohunkohun ti o nitunmọ. Ẹnikọọkan wa kan nilo lati mọ amuyẹ rẹ, gbedeke agbara rẹ ati awọn nkan ti o wa ni arọwọto rẹ ti o le fi ṣiṣẹ ni, ki o si wo bi o ti ṣe le lo awọn nkan wọnyi lati pọ si ni ọrọ ati iṣẹ rere.
Amọ bi a ti ṣe ri ninu ààlọ́ ti Jesu pa fun wa yi, ẹni ti o ba ya ọlẹ ko ni ṣe ohunkohun pẹlu amuyẹ rẹ, agbara rẹ ati awọn nkan ti o wa ni arọwọto rẹ lati jẹ ki aye dara si fun un ati fun awọn miran. Eyi ni a si ri aridaju rẹ lara ọmọ-ọdọ ti oluwa rẹ fun ni talẹnti kan. Ọkunrin yi ko ṣe ohunkohun pẹlu talẹnti kan ti a fun un. Nṣe ni o ri mọlẹ sibikan.
Ki ni idi ti o ṣe ri talẹnti tirẹ mọlẹ, ti ko si ṣiṣẹ pẹlu rẹ bi awọn meji yoku, ki o si sọ ọ di pupọ si? Ọpọ awọn oniwaasu ni o gba wipe idi ti ọkunrin yi fi ṣe bayẹn ni pe owo ti a fun kere jọjọ loju rẹ, nitoripe talẹnti kan pere ni. Amọ bi a ti wa ṣe sọ siwaju, ọpọlọpọ owo ni talẹnti kan ni asiko ti a n sọ yi. Nitorina, ko ki n ṣe nitoripe owo ti a fun kere ni ko ṣe ṣiṣẹ pẹlu rẹ. Bi oun funrarẹ tilẹ ti ṣe sọ fun oluwa rẹ, idi ti ko fi ṣiṣẹ pẹlu rẹ ni pe ẹru n ba pe oun le padanu owo naa.
Ṣugbọn, nigba ti oluwa rẹ yoo ṣe idajọ rẹ, o pe ni ika ati onilọra, iyẹn, ọlẹ. Lọna wo? Akọkọ, o jẹ ika nitoripe o kan n jẹun ọfẹ, o si n gbe ile ọfẹ ni; ko woye pe o yẹ ki oun naa ni ipa ti yoo ko lati jẹ ki ẹni ti o n ṣe itọju rẹ pọ si ni ọrọ. Ti oluwa rẹ ko ba si pọ si ni ọrọ, bawo ni yoo se le ma ṣe itọju rẹ ati awọn ara ile rẹ yoku? Nitorna, ika ati amọtara-ẹni-nikan ni arakunrin yi. Ekeji, o jẹ ọlẹ nitoripe ko ro ori rẹ rara lati wo ọna ti oun le gba lo owo ọga rẹ lati sọ ọ di pupọ si. Ọga rẹ si fun ni apẹrẹ nkan ti ko ba ti ṣe pẹlu owo naa. O sọ fun pe o le fi si ile ifowopamọsi, ki o ba le pọ si ni ibẹ, ka tilẹ sọ wipe ẹru n ba nitootọ lati ma padanu owo naa. Nitorina, ti a ba n sọrọ nipa ọlẹ, a n sọrọ nipa ika eniyan, alanikankọpọn ati alailedanuro.
Ẹ̀KA ÌGBÉ-AYÉ Ọ̀LẸ
A wa nilo lati mọ wipe ẹlẹkajẹka ni igbe-aye ọlẹ jẹ. Ti a ba tilẹ foju sunnukun wo, ẹka mẹta gboogi ni igbe aye ọlẹ pin si. Ẹka akọkọ ni ẹka ALÁPÁMÁṢIṢẸ́. Awọn ọlẹ ti o wa ni ẹka yi ni awọn ti ko ṣetan lati fi ọwọ wọn tabi ara wọn ṣe ohunkohun ti o nitunmọ lati pọ si ni ọrọ tabi ni rere ṣiṣe. Wọn kan fẹ ma a jẹ ounjẹ ọfẹ, gbe ilẹ ọfẹ, wọ mọto ọfẹ ati bẹẹbẹẹ lọ ni. Irufẹ awọn wọnyi ni Pọọlu n ba sọrọ ni ijọ Tẹsalonika, nigba ti o wi bayi:
“Nitori nigba ti awa tilẹ wa pẹlu yin, eyi ni awa pa lasẹ fun yin pe, Bi ẹnikẹni ko ba fẹ ṣiṣẹ, ki o m a ṣe jẹun. Nitori awa gburoo awọn kan ti o ya ọlẹ laarin yin, ti wọn ko n ṣiṣẹ rara, ṣugbọn ti wọn n tọjule kiri. Njẹ iru awọn ẹni bẹẹ ni awa ti paṣẹ fun, ti a si n rọ ninu Oluwa Jesu Kirisiti. Pe ki wọn ki o maa ṣiṣẹ, lati le maa bọ ara wọn.” (2Tẹsálóníkà 3:10-12)
Njẹ o ri bayẹn? Aṣẹ Ọlọrun ni pe ẹnikẹni ti o ba ya alapamaṣiṣẹ ko lẹtọ si ounjẹ. Nitorina, awọn ọmọ Ọlọrun gan ko gbọdọ ran irufẹ ẹni bayi lọwọ, niwọn igba ti o ba kọ lati fi ọwọ rẹ ṣiṣẹ.
Ẹka igbe-aye ọlẹ keji ni ti ÁLAÌLEÈDÁNÚRÒ. Awọn wọnyi ni gbogbo awọn ti o kọ lati lo ọpọlọ ti Ọlọrun fun wọn lati ṣiṣẹ fun ilọsiwaju aye wọn ati ti awujọ wọn. O wa ṣeni laanu pe ọpọ awa eniyan ni a wa ni ẹka yi. Ọlọrun ti fun wa ni ọpọlọ ti o peye lati ṣiṣẹ. Ṣugbọn a ko ṣetan lati lo ọpọlọ yi lati ronu, ki ọgbọn Ọlọrun ti o wa ninu wa ba a le ṣiṣẹ lati fi awọn igbesẹ ti a le gbe lati tun aye wa ati awujọ wa ṣe ati lati pọ si ni ọrọ ati iṣẹ rere han wa. Oniruuru awawi ni a si le ṣe fun aileedanuro wa. A le sọ wipe a ko raye. A le sọ wipe ko si oluranlọwọ fun wa. Amọ awawi lasan ni awọn nkan wọnyi, wọn ko si le yi otitọ ti o wa ninu pe a ya ọlẹ pẹlu ọpọlọ wa pada.
Ti a ba si wa ya ọlẹ pẹlu ọpọlọ wa, o ṣeeṣe ki a tun ya alapamaṣiṣẹ naa pẹlu. Ọpọ alapamaṣiṣẹ ni o ya ọlẹ pẹlu ọpọlọ wọn. Lotitọ, a ri awọn ti o ma n lo ọpọlọ wọn ti wọn ya alapamaṣiṣẹ. Awọn wọnyi ko mọ ju ki wọn ma sọrọ lọ, ki wọn mu oniruuru aba ati ero wa lori oniruuru nkan ti wọn le ṣe. Amọ ti o ba di ki a fi ara ẹni jin lati ṣiṣẹ lori awọn nkan ti wọn mọ, iwa ọlẹ ati imẹlẹ ti o ti gbe wọn wọ ko ni jẹ ki wọn ṣe nkankan tabi ki wọn gbe gbogbo igbesẹ ti wọn le gbe lati tayọ. Awọn wọnyi yoo kan ma n lala ati riran lori nkan ti wọn le ṣe ni; wọn ko le pọ si ni iṣerere ati iwulo niwọn igba ti wọn ba ya alapamaṣiṣẹ.
Ẹka igbe-aye ọlẹ kẹta ni ti Ọ̀LẸ-Ẹ̀MÍ. Awọn wo ni ọlẹ-ẹmi? Awọn naa ni awọn ti o ya ọlẹ ninu ibaṣepọ wọn pẹlu Ọlọrun. Wayi o, awọn ti o mọ Ọlọrun nikan ni ọrọ yi ba wi. A ko le pe awọn ti ko mọ Ọlọrun, ti ko gba Jesu gbọ gẹgẹ bi Oluwa ati Olugbala wọn ni ọlẹ-ẹmi. Awọn ti o mọ Ọlọrun nipasẹ igbagbọ ninu Jesu, ti wọn si ni ibaṣepọ pẹlu rẹ ni a le pe ni ọlẹ-ẹmi.
Ki wa ni idi ti wọn fi jẹ ọlẹ-ẹmi? Wọn jẹ ọlẹ-ẹmi nitoripe wọn ko ma ṣe amulo ti o peye oore-ọfẹ Ọlọrun tabi awọn ipese rẹ lati jẹ irufẹ ẹni ti O fẹ ki wọn jẹ laye yi ati lati ṣe awọn iṣẹ ti O fẹ ki wọn ṣe. Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, akọkọ, ifẹ Ọlọrun ni pe ki gbogbo awọn ti o gbagbọ ninu Jesu dabi rẹ ni gbogbo ọna, ni ọrọ ati ni iṣe (Róòmù 8:29; Éfésù 4:11-16). Ekeji, ifẹ rẹ ni ki a ṣe gbogbo iṣẹ ti O tun wa da ninu Kirisiti Jesus lati ṣe, awọn iṣẹ ti O ti ya sọtọ fun olukuluku wa lati ṣe ki a to fi idi aye yi lọlẹ (Éfésù 2:10).
Ọna wo wa ni a gba lati da ohun gbogbo ti Ọlọrun fẹ ki a da ati lati ṣe gbogbo iṣẹ ti O fẹ ki a ṣe? Nipa ṣiṣe amulo oore-ọfẹ rẹ, iyẹn gbogbo awọn ipese rẹ fun wa. Bibeli ṣọ wipe, “Gẹgẹ bi agbara Ọlọrun ti fun wa ni ohun gbogbo ti i ṣe ti iye ati ti iwa-bi-Ọlọrun, nipa imọ ẹni ti o pe wa nipa ogo ati ọla nla rẹ.” (2Pétérù 1:3) Njẹ o ri bayẹn? Ohun gbogbo ti a nilo lati gbe igbe aye ti Ọlọrun fẹ ki a gbe ni O ti pese fun wa. Lọna wo? Nipasẹ Ẹmi mimọ rẹ ati ninu Kirisiti Jesu.
Amọ ti a ko ba mura, ki a si ṣe giri lati ṣe amulo gbogbo awọn nkan ti Ọlọrun ti pese fun wa, ko si bi a ti ṣe fẹ da ohun gbogbo ti O fẹ ki a da, ki a si tun ṣe ohun gbogbo ti O fẹ ki a ṣe. Eyi yoo si jasi pe ọlẹ ni wa ninu ẹmi. O wa ṣeni laanu pe ọpọ awa ti a jẹ ọmọ Ọlọrun loni ni a jẹ ọlẹ-ẹmi. Idi ni yi ti a ko fi le gbadura bi o ti tọ ati bi o ti yẹ, ti a ko fi fi ara wa jin fun ọrọ Ọlọrun bi o ti tọ ati yẹ, ti a ko fi ara wa jin fun ibaṣepọ pẹlu awọn ọmọ Ọlọrun ti a jọ wa ninu ijọ lọna ti o peye, ti a ko si tun fi ara wa jin fun iṣẹ isin bi o ti ṣe yẹ. Ṣe a wa ro wipe a le ṣeeṣi da ohun gbogbo ti Ọlọrun fẹ ki a da ni? Abi ṣe a ro wipe awọn ẹbun ẹmi ati amuyẹ miran ti Ọlọrun fun wa yoo lo ara wọn lati ṣe awọn iṣẹ ti Ọlọrun fẹ ki a ṣe ti a ko ba lo wọn ni? Eyi ko le ṣeeṣe.
Ki a si ma wo o, ara idi ti ọpọ wa fi jẹ ọlẹ-ẹmi ni pe a jẹ ọlẹ nipa ti ara pẹlu. O ṣeeṣe ki eniyan jafafa nipa ti ara amọ ki o jẹ ọlẹ-ẹmi. Amọ eni ti o ba ti ya ọlẹ nipa ti ara, ti o ya alapamaṣiṣẹ tabi alaileedanuro ko le jafafa ninu ẹmi rara. Ki ni Jesu sọ lori eyi? O sọ wipe, “Njẹ bi ẹyin ko ba ṣe oloootọ ni mamoni aiṣootọ, taa ni yoo fi ọrọ tootọ si ikawọ yin.” (Luuku 16:11) Eyi n jẹ ki o ye wa pe ẹni ti ko ba jafafa nipa nkan ti ara ko le jafafa nipa nkan ti ẹmi. O si tun jasi pe ẹni ti o ba ya ọlẹ nipa ti ara ko le jafafa nipa nkan ti ẹmi pẹlu. Nitorina, ti a ba wo aye gbogbo awa ti a ya ọlẹ-ẹmi daradara, afaimọ ki a ma ri wipe a ya ọlẹ ati onimẹlẹ nipa ti ara naa pẹlu.
Ọrọ Ọlọrun si wa n sọ fun wa pe ko ye ki eyi ri bẹ. Ninu akọsori wa, o sọ fun wa pe, “Ni ti iṣẹ ṣiṣe, ẹ ma ṣe ọlẹ; ẹ ma fi itara sin Oluwa.” (Róòmù 12:11) Njẹ o ri bayẹn? Nipa ti ara Ọlọrun ko fẹ ki a jẹ ọlẹ. Nipa ti ẹmi naa n kọ? Ko fẹ ki a jẹ ọlẹ! Dipo bẹẹ, O fẹ ki a ma fi itara sin in. A tilẹ tun sọ eyi fun wa ninu bibeli: “Ki ẹ ma ṣe di onilọra, ṣugbọn alafarawe awọn ti wọn ti ipa igbagbọ ati suuru jogun awọn ileri.” (Hébérù 6:12) Ṣe o ri bayi? Ọlọrun ko fẹ ki a jẹ onilọra tabi ọlẹ nipa ti ara tabi nipa ti ẹmi rara. Nṣe ni O fẹ ki a jẹ alafarawe awọn ti wọn ti ipa igbagbọ ati suuru jogun awọn ileri rẹ.
Awọn wo ni yoo jogun ileri Ọlọrun? Awọn ti o jafafa ninu ẹmi ni ati nipa ti ara ni. Awọn wo ni yoo da ohun gbogbo ti Ọlọrun fẹ ki wọn da laye yi? Awọn ti o jafafa ninu ẹmi ni ati nipa ti ara ni. Awọn wo si ni yoo gbe gbogbo iṣẹ ti Ọlọrun fẹ ki wọn ṣe laye yi ṣe? Awọn ti o jafafa nipa ti ara ati nipa ti ẹmi ni. Nitorina, gbe ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu iwa ọlẹ tabi imẹlẹ ju danu ninu aye rẹ. Si jẹ ki ọrọ Ọlọrun fọ ọ mọ, ki iwọ naa ba le jẹ ẹni ti Ọlọrun fẹ ki o jẹ ni ọna ti o peye (Jòhánù 15:3).
EWU
Ṣe a wa ri ewu ti o sorọ mọ ki a ya ọọlẹ bi, yala nipa ti ara tabi nipa ti ẹmi? Bẹẹni! Laara awọn ewu ti o si sorọ mọ ni iwọnyi:
– Kò le sí ìlọsíwájú nínú ayé wa: Awọn ti o ba ya ọlẹ, paapaa-julọ nipa ti ẹmi, ko le ni ilọsiwaju ti o wa ni ibamu pẹlu ete ati ifẹ Ọlọrun fun aye wọn. Idi si ni pe wọn ko ni gbe awọn igbesẹ igbagbọ ti sorọ mọ adura gbigba, ṣiṣe aṣaro ninu ọrọ Ọlọrun, ẹkọ kikọ ati bẹẹbẹẹ lọ ti o yẹ ki wọn gbe. Bi a ti ṣe ri ninu abala bibeli ti a n lo fun ẹkọ yi, iranṣẹ ọlẹ ti ko ṣe ohunkohun pẹlu owo ti a fun un ko ni ilọsiwaju. Nigbati ti oluwa wọn n gbe awọn yoku rẹ ga, nṣe ni o ni ki wọn lọ fi oun pamọ sinu tubu, nibiti ẹkun oun ipayinkeke gbe wa. Ọpọ lo si wa ninu tubu aini, airijẹ, airimu ati idojuti loni nitoripe wọn ya ọlẹ nipa ti ara tabi nipa ti ẹmi. Ti o ba si wa jẹ wipe iwọ naa wa lara irufẹ awọn wọnyi, nṣe ni ko yara tete gbe aṣọ imẹlẹ rẹ ju danu, ki o si wa nkan ṣe. Ọlọrun yoo si boju aanu wo ọ, yoo si tun tu ọ silẹ kuro ninu ahamọ ìṣẹ́ ati ìdàmú ti o wa.
– Ìlọsíwájú kò le bá àwùjọ wa: Nibi ti ọpọ awọn ti o wa ni awujọ ba ti ya ọlẹ, ko le si ilọsiwaju ti o peye ni awujọ naa. Awọn ole, jaguda, gbajuẹ, ajinigbe ati bẹẹbẹẹ lọ ni yoo pọ ju nibẹ. Nitorina, yatọ si pe wọn ko ni ni ilọsiwaju, ibalẹ ọkan yoo tun jina si wọn ni ibẹ. Irufẹ awujọ bi eleyi ko wa ni kuro ni ipo ẹru awọn ti o n ṣiṣẹ, ti o n lo ọpọlọ wọn, bi awọn wọnyi ko tilẹ mọ Ọlọrun. Wo orilẹ-ede Naijeria, fun apẹrẹ. Ọpọ loni ni ko fẹ lo ọpọlọ ti Ọlọrun fun wa lati ṣiṣẹ ti to tọna ki wọn to lowo. Owo kiakia, owo ojiji ati owo faaji ni ọpọ, ati ọdọ ati agba, n wa kiri. Awọn adari ẹsin gan ko gbẹyin ninu eyi. Nitorina, ole jija, iṣẹṣo owo, ilọnilọwọgba, riba gbigba, iṣẹ aṣẹwo ati bẹẹbẹẹ lọ ni o gbilẹ kan. Ifarahan igbe ayẹ ọlẹ si ni awọn nknan wọnyi, eyi ti ko si jẹ ki idagbasoke ati ilọsiwaju ti o ni itunmọ ba aye wa.
– Ọpọlọ wa yóò sùnlọ: Yiya ọlẹ ma n jẹ ki ọpọlọ eniyan sunlọ ni, bi o ti wu ki ọgbọn pọ to ninu ọpọlọ naa. A ri wipe iranṣẹ ti ko ṣe ohunkohun pẹlu owo ti ọga rẹ fun ko lo ọpọlọ rẹ rara. Gẹgẹ bi ọga rẹ ti ṣe fi ye e, bi o tilẹ jẹ wipe ẹru n ba pe ki o ma padanu owo naa lori okowo ti ko lere, o ni anfaani lati ko owo naa si ile ifowopamọsi. Eyi ko ba si jẹ ki o gba owo naa pade pẹlu ele. Ṣugbọn nitoripe o ya alapamaṣiṣẹ ati ẹni ti ko ṣetan lati lo ọpọlọ rẹ, nṣe ni ọpọlọ rẹ sunlọ patapata, ti ko si ri awọn anfaani ti o wa fun lati sọ owo ti a fun di ilọpo. Ti awa naa ba fi aye gba imẹlẹ ninu aye wa, ọpọlọ wa ko ni ṣiṣẹ debi wipe yoo ri awọn anfaani ti o wa ni ayika wa lati ṣe rere laye. Nṣe ni a o kan joko soju kan, ti a o ma ṣe aroye pe ko si ẹnikẹni ti o fẹ ran wa lọwọ.
– Ìpàdánù àwọn ǹkan tí a fi fún wa: Bi a ti tun ṣe ri ninu owe awọn iranṣẹ mẹta ti Jesu Oluwa wa sọ yi, nitoripe iranṣẹ kẹta ti a fun ni talẹnti kan owo ya ọlẹ, ti ko si ṣe nkankan pẹlu owo ti a fun un, oluwa rẹ sọ wipe ki a gba talẹnti naa lọwọ rẹ, ki a si fi fun ẹni ti o ti ni mẹwa. Eyi si n fiye wa pe Ọlọrun le gba awọn anfaani ti O fun wa lati pọ si ni rere kuro lọwọ wa, ki O si ko wọn fun ẹlomiran, ti a ba ya ọlẹ. Ọlọrun ko nilo lati gba ọpọlọ tabi amuyẹ wa ki o to ṣe eyi. Oluwa ọmọ-ọdọ yẹn ko gba ọpọlọ rẹ tabi agbara tabi amuyẹ rẹ kuro lọwọ rẹ. Ṣugbọn o gba anfaani ti O fun kuro lọwọ rẹ. Idi si ni yi ti awọn ti ko ba ya ọlẹ ninu ẹmi tabi ninu ara ṣe ma n pọ si ni rere, ti awọn ti o ya ọlẹ yoo si ma dinku si ni ilọsiwaju ati iwulo.
– Èṣù yóò ráyè si láti má a ṣiṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀: Bi a ti ṣe sọ sẹyin, ara awọn ẹka igbe aye ọlẹ ni ọ̀lẹ-ẹ̀mí. Ẹni ti o ba si ya ọlẹ nipa ti ẹmi ko ni gbadura, ṣe aṣaro ninu ọrọ Ọlọrun tabi darapọ mọ awọn ọmọ Ọlọrun miran fun ìgbéró ni ọna ti o yẹ. Dipo eyi, nṣe ni wọn yoo maa wa awọn wolii tabi alufa ti wọn yoo fi ojuṣe adura gbigba wọn kọ lọrun. Nitorina, nṣe ni ara ma n ya eṣu lati ṣiṣẹ ninu aye wọn. O ti mọ wipe wọn ya ọlẹ, wọn ko si ni doju ija kọ oun. Boya idi ti aaye ṣe gba eṣu lati ṣiṣẹ ninu aye iwọ naa ni pe o ya ọlẹ nipa ti ẹmi. Nṣe ni ki o ronupiwada, ki o si mura giri lati gbe gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ lati bẹrẹ si ni rin ninu iṣẹgun lori iṣẹ eṣu. Aijẹbẹ, eṣu yoo kan ma jẹ ọ lole ati pọn ọ loju bi o ti ṣe fẹ ni. Nitorina, ilọsiwaju, alaafia, ibalẹ-ọkan ati igbega ti o yẹ ki o jẹ tirẹ ko ni le jẹ tirẹ.
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Ọlọrun ko fẹ awọn ọmọ rẹ fun igbe aye ọlẹ tabi ti imẹlẹ. Nitorina, ohun gbogbo ti o ba ni i ṣe pẹlu iwa ọlẹ tabi imẹlẹ, yala nipa ti ara ni tabi nipa ti ẹmi ni a gbọdọ yẹra fun. Aijẹbẹ, ilọsiwaju ti o yẹ ki o ba aye wa ati awujọ wa ko ni ba wọn.
ÌBÉÈRÈ
– Njẹ o ro wipe ẹkọ yi ṣe pataki fun awọn ọmọ Ọlọrun bi?
– Yatọ si awọn ewu ti o sorọ mọ igbe aye ọlẹ ti a mẹnuba ninu ẹkọ yi, awọn ewu miran wo ni o tun ro wipe o sorọ mọ?
Láti ọwọ́ Johnson O. Lawal
Copyright © 2024 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07025105978)
ÀKỌ́RÍ: MÁ JẸ́ KÓ DÍBÀJẸ́ | ÀYỌKÀ: ÌSÍKÍẸ̀LÌ 28:11-19 | ỌJỌ́RÚ 22, ÈBÌBÍ 2024
ÀKỌ́SÓRÍ: “Jẹ ki awọn obirin yin dakẹ ninu ijọ: nitori a ko fi fun wọn lati sọrọ, ṣugbọn jẹ ki wọn wa labẹ itẹriba, gẹgẹ bi ofin pẹlu ti wi.” (1Kọ́ríntì 14:34)
Ọkan rẹ gberaga nitori ẹwa rẹ. Iwọ si ba ọgbọn rẹ jẹ nitori didara rẹ. Nitori naa mo le ọ sori aye; mo si sọ ọ di awò oju niwaju awọn ọba.” (Ìsíkíẹ̀kì 28:17)
Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ
Ọrọ Ọlọrun jẹ ki o ye wa pe ko si ohunkohun ti ẹnikẹni le rigba laye yi tabi ni ọrun tabi ni isalẹ omi lalai jẹ wipe Ọlọrun ba fi fun un (Jòhánù 3:27). Idi si ni pe Ọlọrun ni ẹlẹda ohun gbogbo. Ikawọ rẹ si ni ohun gbogbo wa. Ko wa si bi a ti ṣe gbọn to, ja fafa to tabi lakaka to, kiki ohun ti O ba jẹ ki o tẹ wa lọwọ naa ni yoo jẹ tiwa. Bẹẹ si tun ni pẹlu, ko si bi a ti ṣe ṣoogun to tabi lo iwa ipa tabi jagidijagan to, kiki ohun ti Ọlọrun ba jẹ ki o tẹ wa lọwọ naa ni yoo tẹ wa lọwọ. Idi niyi ti a tun ṣe sọ fun wa ninu bibeli pe ki a ma fi igbẹkẹle wa sinu ẹnikẹni ati sinu ohunkohun bi ko ṣe sinu Ọlọrun (Jeremáyà 9:23-24). Idi si ni pe Ọlọrun ni O ma n fun eniyan ni ohun gbogbo lọfẹ ati lọpọlọpọ fun igbadun aye wọn (1Tímótì 6:17).
Yatọ si iyẹn, bi a tun ti ṣe ri ninu bibeli, ohunkohun ti Ọlọrun ba fi fun eniyan, daradara ati pipe ni. Ọlọrun ko ki fun eniyan ni nkan ti idibajẹ ti wọ inu rẹ tabi nkan ti yoo pa a lara tabi fi ikoro sinu aye rẹ, ti ko ba ki i ṣe wipe ẹni naa mura lati lọ Ọlọrun lọwọ gba (Ìwé Òwe 10:22; Jákọ́bù 1:17). Fun apẹrẹ, ọkunrin afọju kan wa ti Jesu la oju rẹ lọjọ kan. Ṣugbọn ki oju rẹ to bẹrẹ si ni riran daradara, igba meji ọtọọtọ ni Jesu gbọwọ le ni oju. Ki ni idi? Nigba ti O kọkọ gbe ọwọ le ni oju, O bere lọwọ rẹ pe ṣe o ti n riran. Idahun rẹ si ni pe ohun ri awọn eniyan ti wọn dabi igi ti o n rin. Ṣe Jesu wa sọ wipe ki o ma lọ si ile rẹ layọ ati alaafia ati wipe diẹ naa to ninu nkan oninkan? Rara o! Nṣe ni O tun gbe ọwọ le loju ni igba keji, ki o ba le e riran daradara. O si bẹrẹ si ni riran daradara. (Wo: Máàkù 8:22-26)
Eyi si jẹ ki o ye wa pe Ọlọrun ko ki i ṣe iṣẹ aabọ. Aṣepe ni gbogbo iṣẹ rẹ. Apẹrẹ keji ti a tun ri ninu bibeli ni ti Adamu. A o ri wipe Ọlọrun tikararẹ lo kọkọ sọ wipe ko dara ki Adamu nikan maa gbe ati wipe Oun yoo ṣe oluranlọwọ ti o dabi tirẹ fun. O si ṣe bẹẹ gẹgẹ fun ọkunrin yi. O ṣe ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu aye rẹ ni aṣepe. Eyi ko wa jasi pe Adamu ko pe to tabi dara to nigba ti Ọlọrun da a. O pe to. O si dara to. Amọ, ete Ọlọrun ki O to da a nipe takọ-tabo ni eniyan yoo jẹ lorilẹ aye. Eyi si ṣe pataki fun ajumọkẹgbẹpọ ati igberu si awa eniyan. Nitorina, Ọlọrun kan yanana iṣẹ ti O ti ṣe pe silẹ ni nipa mimu Efa jade lara Adamu ni. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 2:18-25)
Nitorina, ti a ba ri ẹni ti a bi pẹlu ailera kan tabi omiran, a gbọdọ mọ wipe ko ki i ṣe Ọlọrun ni ko da ẹni naa pe tabi ti O ṣiṣẹ aabọ lori rẹ. Eṣu tabi awọn eniyan ti o n ya a lo ni o fi idibajẹ sinu aye ẹni naa. Ni kukuru, ohunkohun ti o ba ni i ṣe pẹlu aleebu tabi akude ninu aye awọn eniyan, a gbọdọ mọ wipe ko ti ọwọ Ọlọrun waye. Nitoripe Ọba Alaṣepe ni Ọlọrun jẹ. (Wo: Jòhánù 9:1-7)
Niwọn igba ti eyi si wa ri bẹ, o ṣe pataki ki awa ti a jẹ ọmọ Ọlọrun kọ lati ma jẹ ki ohunkohun ti Ọlọrun ba fun wa dibajẹ. Idi si ni yi fun ẹkọ bibeli yi. A fẹ wo awọn nkan ti Ọlọrun le fun wa ti o le dibajẹ mọ wa lọwọ ati awọn nkan ti o le fa ki awọn nkan wọnyi dibajẹ mọ wa lọwọ. Oye nkan wọnyi yoo jẹ ki a le paramọ, ki a si gbaradi lati ma fi aye gba ohunkohun ti o ni i ṣe pẹlu idibajẹ ninu aye wa. Adura mi si ni pe Ọlọrun yoo kun wa fun okun lati ṣe amulo ti o peye oye yi. Amin.
KÍ NI Ó LE DÍBÀJẸ́
Ki wa ni awọn nkan naa ti Ọlọrun le fun wa ti o si le dibajẹ mọ wa lọwọ? Ẹmi mimọ nikan ni ẹni naa ti Ọlọrun le fun eniyan ti ko le dibajẹ ninu aye rẹ. Yatọ si Oun, ko si ohunkohun ti a le fun wa ti ko le dibajẹ mọ wa lọwọ. Fun apẹẹrẹ, ẹṣẹ bibeli ti a fi ṣe akori ẹkọ yi sọ wipe:
“Ọkan rẹ gberaga nitori ẹwa rẹ. Iwọ si ba ọgbọn rẹ jẹ nitori didara rẹ. Nitori naa mo le ọ sori aye; mo si sọ ọ di awò oju niwaju awọn ọba.” (Ìsíkíẹ̀kì 28:17)
Tani a n sọrọ nipa nibiyi? Ọba ilu kan ti a n pe ni Taya tabi Tire ni. Ṣugbọn ti a ba wo awọn nkan ti a sọ nipa ọba yi finifini ninu iwe Isikiẹli yi, a o ri wipe ẹni ti a n sọrọ nipa kọja eniyan lasan. Angẹli Ọlọrun ti a n pe ni Satani gan an ni a n sọrọ nipa. Iwo naa wo diẹ lara nkan ti a sọ nipa rẹ gẹgẹ bi ọba Tire:
“Ọrọ Oluwa si tun tọ mi wa wi pe, Ọmọ eniyan pohun rere sori ọba taya, ki o si wi fun un pe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Iwọ fi edidi di iye naa, o kun fun ọgbọn, o si pe ni ẹwa. Iwọ ti wa ni Edeni ọgba Ọlọrun; oniruuru okuta iyebiye ni ibora rẹ, sadiu, topasi, dayamọndi, bẹrili, onisi, jasipa, safa, emeradi, kabu-nkili ati wura: iṣẹ ilu rẹ, ati ti fere rẹ ni a pese ninu rẹ ni ọjọ ti a da ọ. Iwọ ni kerubu ti a yan ti a si bo; emi si ti gbe o kalẹ: iwọ wa lori oke mimọ Ọlọrun; iwọ ti rin soke rin sodo laarin okuta ina.” (Ìsíkíẹ̀kì 28:11-14)
Njẹ o ri bayi pe Kerubu Ọlọrun ni ẹni ti a pe ni ọba Tire ninu awọn ẹsẹ bibeli wọnyi? Ki wa lo de ti a ṣe pe ni ọba Tire? A pe ni ọba Tire ninu iwe yi lati kan jẹ ki o ye wa pe ọpọ igba ni o jẹ wipe Satani ni o ma n ṣakoso awọn ilu, ipinlẹ ati orilẹ-ede wa. Lotitọ, a le ni adari ti gbogbo eniyan mọ lori ilu kan tabi agbegbe kan. Ṣugbọn niwọn igba ti ẹni naa ko ba ti fi ara rẹ jin fun Ọlọrun, o di dadan ki Satani, ti o jẹ ọmọ alade aye yi, gba ọkan ẹni naa, ki o si bẹrẹ si ni lo lati sakoso awọn ti o wa ni abẹ rẹ. Eyi si ni alaye fun bi awọn adari ṣe ma n ṣiwawu, ti wọn a si ma ṣe awọn nkan ti o tojusuni, ti wọn ko si ni bikita rara.
Ki a ma fọrọgun, ọba Tire yi, iyẹn Satani, kun fun ọgbọn, o si tun pe ni ẹwa nigba ti Ọlọrun da a. A ti sọ tẹlẹ wipe ẹnikẹni tabi ohunkohun ti Ọlọrun ba da, daradara ati pipe ni. Bẹẹ naa si ni o ri fun Eṣu naa nigba ti Ọlọrun da a. O lẹwa. O si lọgbọn. Eyi si jẹ ki o ye wa pe ẹbun Ọlọrun ni ẹwa. Ẹbun Ọlọrun si ni ọgbọn naa pẹlu. Ko tilẹ si ohun daradara kankan ti a le ni lọwọ ti ko ki i ṣe ẹbun Ọlọrun.
Nikukuru, nigba ti o ya, Eṣu ba ọgbọn ati ẹwa ara rẹ jẹ. Nitorina, Ọlọrun le kuro ni ipo ti o fi si. O wa di alarinkinri. Amọ koko nkan ti a fẹ fayọ ninu eyi ni pe ọgbọn wa le dibajẹ. Bẹẹ si ni pẹlu, ẹwa wa le dibajẹ. Eyi ko wa jasi pe a ko ni ọgbọn lori mọ tabi wipe a ko lẹwa mọ. Dipo bẹẹ, nkan ti o tunmọ si ni pe ọgbọn ati ẹwa wa ko wulo fun ogo Ọlọrun, ko si le mu ete rẹ fun aye wa tabi fun aye awọn miran ṣẹ.
Wayi o, ko ki i ṣe ọgbọn tabi ẹwa wa nika ni o le dibajẹ. Ọrọ wa, dukia wa ati ipo wa naa le dibajẹ. Fun apẹrẹ, Jemisi sọ eyi si awọn ọlọrun ninu lẹta rẹ:
“Ẹ wa nisinsinyi, ẹyin ọlọrọ, ẹ maa sọkun ki ẹ si maa pohunrere ẹkun nitori oṣi ti n bọwa ta yin. Ọrọ yi dibajẹ, kokoro si ti jẹ aṣọ yin. Wura oun fadaka yin dibajẹ; ibajẹ wọn ni yoo si ṣe ẹlẹrii si yin, ti yoo si jẹ ẹran ara yin bi ina. Ẹyin ti ko iṣura jọ de ọjọ ikẹyin. Kiyesi i, ọya awọn alagbaṣe ti wọn ti ṣe ikore oko yin, eyi ti ẹ ko san, n ke rara; ati igbe awọn ti o ṣe ikore si ti wọ inu eti Oluwa awọn ọmọ-ogun. Ẹyin ti jẹ adun ni aye, ẹyin si ti fi ara yin fun aye jijẹ; ẹyin si mu ara yin sanra de ọjọ pipa. Ẹyin ti da ẹbi fun olododo, ẹ si ti pa a; oun ko si kọ oju ija si yin.” (Jákọ́bù 5:1-5)
Ki ni a ri ninu awọn ẹṣẹ bibeli yi? Oun naa ni pe idibajẹ le ba ọrọ ati ipo wa. Nkan ti a n sọ nibi wa kọja ki dukia wa tabi owo wa jẹra mọlẹ. O ni i ṣe pẹlu pe ki a ma lo wọn fun ogo ati ete Ọlọrun. Itunmọ eyi ni pe ohunkohun ti a ko ba lo fun ete ati ogo Ọlọrun ati ohun yowu ti a ba n lo lodi si ogo Ọlọrun ti dibajẹ mọ wa lọwọ.
Siwaju si, idibajẹ le wọ agọ ara wa. Lọna wo? Nipasẹ aisan tabi ailera idibajẹ le wo agọ ara eniyan. Ọlọrun ko da agọ ara wa fun aisan ati ailera bi a ti ṣe sọ ninu bibeli. Nṣe ni O da agọ ara wa lati jẹ ibugbe rẹ, lati jẹ tẹmpili rẹ. Ti aisan tabi ailera ba wa ba agọ ara, ko ni jẹ ki eniyan le lo agọ ara naa lọna ti o pe lati ṣe ifẹ Ọlọrun. Aisan, ailera tabi ipalara tilẹ le sọ eniyan di ẹni ti ko wulo fun Ọlọrun rara. Nitorina, idibajẹ ni aisan, ailera ati ipalara jẹ ninu agọ ara eniyan. (Wo: Jóòbù 33:19-22; 1Kọ́ríntì 3:16-17)
Aisan, ailera ati ipalara nikan wa kọ ni o le fi idibajẹ sinu agọ ara eniyan; iṣekuṣe naa le fi idibajẹ sinu rẹ. Wo nkan ti Pọọlu sọ lori eyi:
“Ẹ maa ṣa fun agbere. Gbogbo ẹṣẹ ti eniyan n da o jẹ ti ode ara; ṣugbọn ẹnikẹni ti o n ṣe agbere, o n ṣẹ si ara oun tikararẹ. Tabi, ẹyin ko mọ pe ara yin ni tẹmpili Ẹmi mimọ, ti n bẹ ninu yin, ti ẹyin ti gba lọwọ Ọlọrun. Ẹyin ki i ṣi i ṣe ti ara yin mọ.” (1Kọ́ríntì 6:19)
Ṣe o ri bayi pe ẹbun Ọlọrun ni agọ ara wa jẹ fun wa? Ṣe o tun ri wipe tẹmpili Ọlọrun ni agọ ara wa? Nitorina, ti o ba n ṣe agbere, nṣe ni o n fi idibajẹ sinu agọ ara rẹ, ti o si n ba tẹmpili Ọlọrun jẹ.
Yatọ si awọn nkan ti a ti mẹnuba yi, idibajẹ tun le wọ inu awọn ibaṣepọ wa naa pẹlu. Idibajẹ le wọ inu igbeyawo. Idibajẹ le wọ inu aye awọn ọmọ. Ẹbun Ọlọrun ni awọn ọmọ wa, ọkọ wa, aya wa ati obi wa jẹ fun wa. Ẹbun si tun ni awọn ọmọ ijọ wa, awọn adari ijọ wa ati bẹẹbẹẹ lọ jẹ fun wa pẹlu. Ti a ko ba si wa ni oye pe idibajẹ le wọ inu ibaṣepọ wa pẹlu awọn wọnyi, yoo ti wọle sinu rẹ tan ki a to mọ ohun ti o n ṣẹlẹ.
Iṣẹ isin wa nkọ? Idibajẹ naa le wọ eyi. Idibajẹ le wọ iwaasu wa. Idibajẹ le wọ ififunni wa. Pọọlu sọ eyi fun wa ninu lẹta rẹ si awọn ara Galatia:
“Nitori ẹni ti o ba n furugbin sipa ti ara rẹ, nipa ti ara ni yoo ka idibajẹ; ṣugbọn ẹni ti o ba n funrugbin sipa ti Ẹmi, nipa ti Ẹmi ni yoo ka iye ainpẹkun.” (Gàlátíà 6:8)
Njẹ o ri bayẹn? Ko ki i ṣe gbogbo iṣẹ isin ni o mọ niwaju Ọlọrun. Fun apẹrẹ, idibajẹ wọ ẹbọ Kaini. Nitorina Ọlọrun ko tẹwọ gba a. Bakan naa, idibajẹ wọ iṣẹ isin Ananaya ati Safira aya rẹ. Nitorina, Ọlọrun ko tẹwọ gba a. O tilẹ tun yọri si iku fun wọn. Ti a ko ba si wa mọ pe idibajẹ le wọ inu iṣẹ isin wa, yoo ti wọle tan sinu rẹ ki a to mọ.
ORÍSUN ÌDÍBÀJẸ́
Ọna wo wa ni idibajẹ le gba wọ inu aye wa, ọgbọn wa, ẹwa wa, ipo wa, ọrọ wa, ibaṣepọ wa ati ohun yowu ti a le ti rigba lati ọwọ Ọlọrun? Bi a ti ṣe ri ninu awọn ẹṣẹ bibeli ti a ti mẹnuba ṣẹyin, nipasẹ Satani ni idibajẹ ṣe ma n wọnu aye awọn eniyan. Satani gan an ni orisun idibajẹ. Ọdọ rẹ ni idibajẹ ti ṣẹ wa. Wo nkan ti a sọ nipa rẹ lẹẹkan si:
“Ọkan rẹ gberaga nitori ẹwa rẹ. Iwọ si ba ọgbọn rẹ jẹ nitori didara rẹ. Nitori naa mo le ọ sori aye; mo si sọ ọ di awò oju niwaju awọn ọba.” (Ìsíkíẹ̀kì 28:17)
Ki ni o fi idibajẹ sinu aye Satani? Ki ni o sọ ọgbọn ati ẹwa rẹ di ibajẹ? Igberaga ni! Igberaga si Ọlọrun ni o ko ba Satani. Nitorina, olori nkan ti o n fi idibajẹ sinu aye awọn eniyan ni igberaga si Ọlọrun. Ọdọ Satani si ni o ti n wa. Oun ni o ma n gbe ero igberaga si ọkan awọn eniyan. Oun ni o ma n fun wọn ni ero wipe awọn ko nilo Ọlọrun ninu aye wọn tabi wipe awọn gbọn ju Ọlọrun lọ. Wo nkan ti Ọlọrun ti ẹnu Aisaya sọ lori eyi:
“Bawo ni iwọ ti ṣe ṣubu lati ọrun wa, iwọ Lusiferi, irawọ owurọ! Bawo ni a ti ṣe ge ọ lu ilẹ iwọ ti o ti ṣe awọn orilẹ-ede ni apa! Nitori iwọ ti wi ni ọkan rẹ pe, Emi o goke lọ si ọrun, emi o gbe itẹ mi ga kọja irawọ Ọlọrun: emi o si jokoo lori oke ijọ eniyan ni iha ariwa: Emi o goke kọja giga awọsanma: emi o dabi ọga ogo julọ.” (Àísáyà 14:12-14)
Ṣe o ti ri iṣoro Eṣu bayi? O fẹ duro gẹgẹ bi Ọlọrun lori aye ara rẹ. Gbogbo ibi ti awọn eniyan ba si ti n gbiyanju lati di Ọlọrun fun ara wọn, ko si ni ki idibajẹ ma ba ohun ti wọn ba ni. Ranti pe idibajẹ ba aye iran eniyan nigbati Adamu ati Efa naa gbiyanju lọjọ kini ana lati di Ọlọrun lori aye ara wọn. Igberaga ni eyi. O si jẹ ki idibajẹ wọnu gbogbo aye.
Nitorina, olori ohun ti o n fa idibajẹ sinu aye awọn eniyan ni igberaga si Ọlọrun. Igberaga ni ko ni jẹ ki wọn gbọnran si aṣẹ rẹ lori aye wọn, agọ ara wọn, ibaṣepọ wọn, dukia wọn, ipo wọn ati bẹẹ bẹẹ lọ. Niwọn igba ti wọn ko ba si ti gbọran si aṣẹ rẹ, o didan ki awọn nkan ti O fun wọn lọfẹ fun igbaye-gbadun wọn dibajẹ mọ wọn lọwọ.
Awọn nkan miran ti o tun n fa idibajẹ sinu aye awọn eniyan ni ifẹkufẹ, ojukokoro, ilara, ẹtanu ati bẹẹbẹẹ lọ. A si wa gbọdọ ti ilẹkun aye wa mọ awọn nkan wọnyi. Aijẹbẹ, wọn yoo ba ọgbọn wa, oye wa, ipo wa ati didara wa jẹ ninu aye yi ati niwaju Ọlọrun. Ranti wipe ojukokoro ni o sọ ipo Sọọlu gẹgẹ bi ọba di ibajẹ mọ lọwọ. Si tun ranti wipe ojukokoro yi kanna ati ifẹkufẹ ni o fi idibajẹ si iṣejọba daradara Dafidi. Nitorina, a gbọdọ ṣe idamọ awọn nkan ti o le sọ ẹbun ati oore-ọfẹ Ọlọrun di ibajẹ mọ wa lọwọ, ki a si yẹra fun wọn.
Ni afikun, Satani funrarẹ ma n gbogun ti awọn eniyan lati sọ nkan ti Ọlọrun fun wọn di ibajẹ mọ wọn lọwọ. O le gbogun ti agọ ara wọn, bi o ti ṣe ṣe pẹlu Joobu ni ọjọ kinni ana. O le mu ki ijamba ṣẹlẹ si awọn eniyan lati pa agọ ara wọn run, ki o ma ba wulo fun Ọlọrun mọ. O si le gbin ero buburu si ọkan awọn eniyan lati gbe awọn igbesẹ ti yoo ba ibaṣepọ wọn jẹ. O wa ku si ọwọ lati ma fi aye gba ohunkohun ti o ni i ṣe pẹlu idibajẹ ninu aye wa. Aijẹbẹ, Eṣu yoo ba gbogbo nkan daradara ti Ọlọrun fun wa jẹ mọ wa lọwọ.
MÁ FI ÀYÈ GBA ÌDÍBÀJẸ́
Ṣe a wa le ṣe nkankan lati ma fi aye gba idibajẹ ninu aye wa? Bẹẹni! A ti jẹ ki o ye wa pe Eṣu ni orisun gbogbo idibajẹ. Nitorina, oun ni a ko gbọdọ fi aye gba ninu aye wa. Ṣe o si wa ṣeeṣe? Bẹẹni, o ṣeeṣe. Ọrọ Ọlọrun sọ nkan wọnyi fun wa lori eṣu:
“Bẹẹ ni ki ẹ ma ṣe fi aaye fun Eṣu.” (Éfésù 4:27)
“Nitori naa, ẹ tẹriba fun Ọlọrun. Ẹ kọ oju ija si Eṣu, oun o si sa kuro lọdọ yin.” (Jákọ́bù 4:7)
“Ẹ maa wa ni airekọja, ẹ maa ṣọra; nitori Eṣu, ọta yin, bi kinniun ti n ke ramuramu, o n rin kaakiri, o n wa ẹni ti yoo pajẹ: Ki ẹyin ki o si kọ oju ija si Esu nipa iduroṣinṣin yin ninu igbagbọ, ki ẹyin ki o mọ pe iya kan naa ni awọn ara yin n jẹ kaakiri aye.” (1Pétérù 5:8-9)
Pẹlu awọn nkan ti a sọ fun wa ninu ọrọ Ọlọrun yi, a ri daju pe ojuṣe wa gẹgẹ bi eniyan ni lati ma fi aaye gba eṣu ninu aye wa. Ojuṣe wa si tun ni pẹlu lati kọ oju ija ṣi pẹlu iduro ṣinṣin, ti a ba kofiri rẹ ni ayika tabi ni agbegbe wa. Amọ ti a ko ba rẹ ara wa silẹ niwaju Ọlọrun, ki a si tẹriba fun awọn aṣẹ rẹ lati ma a tẹle wọn, a ko ni i le kọju ija si eṣu, ki a si lero pe yoo sa fun wa. Ṣugbọn ti a ba rẹ ara wa silẹ niwaju Ọlọrun, a o wa ni ipo ẹni ti yoo le kọju ija si eṣu, ki o si le danu. A si ri wipe ọrọ Ọlọrun sọ wipe yoo sa fun wa, ti a ba kọju ija si. Ọrọ naa ko si wipe yoo sa fun Ọlọrun; dipo eyi, o sọ wipe yoo sa fun wa.
Ni kukuru, ti a ko ba fẹ fi aye gba idibajẹ ninu aye wa, ti a ko ba fẹ ki ohunkohun ti Ọlọrun fi ta wa lọrẹ di ibajẹ mọ wa lọwọ, a gbọdọ mura lati ma fi aye gba eṣu ninu aye wa. Lọna wo? Akọkọ, a ko gbọdọ fi aye gba ninu ero wa. Bibeli sọ wipe:
“Ṣe aapọn lati pa ọkan rẹ mọ, nitori pe lati inu rẹ ni iye ti n sun jade.” (Ìwé Òwe 4:23)
“O si wi pe, Eyi ti o ti inu eniyan jade, eyi ni ni i sọ eniyan di alaimọ. Nitori lati inu , lati inu ọkan eniyan ni ero buburi ti i jade wa, pansaga, agbere, ipaniyan, Ole, ojukokoro, iwa buburu, itanjẹ, wọbia, oju buburu, isọrọodi, igberaga, omugo: Lati inu wa ni gbogbo nnkan buburu wọnyi ti i jade, wọn a si sọ niyan di alaimọ.” (Máàkù 7:20-23)
“Eniyan rere lati inu iṣura rere ọkan rẹ ni i mu ohun rere jade wa, eniyan buburu pẹlu lati inu iṣura buburu ọkan rẹ ni i mu ohun buburu jade wa: nitori lati ọpọlọpọ ohun ti n bẹ ni ọkan ni ẹnu rẹ ti i sọ.” (Lúùkù 6:45)
Nkan ti awọn ẹṣẹ bibeli yi n fi han wa ni pe irufẹ ero ti a fi aye gba ni ọkan wa ni ipa pupọ lati ko lori awọn nkan ti aye wa yoo maa gbe jade, boya rere ni tabi buburu. Irufẹ nkan ti a ba fi aye gba ninu ọkan wa ni yoo sọ boya awọn nkan ti Ọlọrun fun wa bi ẹbun Ẹmi, ipo, oye, ọgbọn ati bẹẹbẹẹ lọ yoo ma ṣiṣẹ fun rere ati fun imuṣẹ ete rẹ tabi yoo di idibajẹ mọ wa lọwọ.
Bawo ni ọgbọn ati ẹwa Eṣu ṣe dibajẹ? Bi a ti ṣe ri ninu awọn ẹsẹ bibeli ti a ti mẹnuba tẹlẹ, nipasẹ ero igberaga ti o fi aye gba ninu ọkan rẹ ni. Iyẹn tunmọ si pe inu ọkan rẹ ni idibajẹ gba wọ aye rẹ, ti o si ba gbogbo awọn ohun dadara ti Ọlọrun fun un jẹ mọ lọwọ.
Ti awa naa ko ba fẹ ki ẹtanu, igberaga, ifẹkufẹ, ojukororo, iṣọtẹ ati awọn iwa eeri miran wọ inu ọkan wa, ki wọn si sọ awọn ẹbun Ọlọrun di nkan idibajẹ mọ wa lọwọ, a gbọdọ ṣe aapọn, bi Solomoni ti sọ fun wa ninu ẹsẹ bibeli yẹn, lati pa ọkan wa mọ. Iyẹn jasi pe ki a mọ irufẹ ẹkọ, ọrọ ati iran ti a o ma fun ọkan wa jẹ. Aijẹbẹ, idibajẹ le ti ara wọn wọle si wa lara.
Yatọ si iyẹn, a tun gbọdọ fi ara wa jin fun ọrọ Ọlọrun, ki a ba le mọ awọn ero ti o lodi si ifẹ rẹ ti a gbọdọ bi wo lulẹ ninu ọkan wa. Idi niyi ti Pọọlu ṣe sọ eyi fun wa:
“Nitori pe bi awa tilẹ n rin ninu ara, ṣugbọn awa ko jagun nipa ti ara. (Nitori ohun ija wa ki i ṣe ti ara, ṣugbọn o ni agbara ninu Ọlọrun lati wo ibi giga palẹ.) Awa n sọ gbogbo iyan-jija ati ohun gbogbo ti o gbe ara rẹ ga si imọ Ọlọrun di asan, awa si n di gbogbo ero ni igbekun wa si abẹ itẹriba fun Kirisiti.” (2Kọ́ríntì 10:3-5)
Njẹ o ri bayẹn? A gbọdọ bi ero gbogbo ti o n ba Ọlọrun jiyan ati eyi ti o n gberaga si ninu aye wa lulẹ, ki a si sọ ọ di asan. Bẹẹ si ni pẹlu, a gbọdọ jẹ ki gbogbo ero ọkan wa tẹriba fun Jesu Kirisiti. Eyi jasi pe ero ọkan wa kankan ko gbọdọ tako tabi lodi si aṣẹ rẹ. Erokero ti o ba ti lodi si aṣẹ rẹ gbọdọ di gbigbe sọnu. Nipa bayi, esu ko ni ri aye wọle sinu aye wa nipa lilo awọn ero ọkan wa lati sọ awọn nkan ti Ọlọrun fun wa di ibajẹ.
Nkan ẹkẹta ti a nilo lati ma a ṣe lati ma fi aye gba idibajẹ awọn nkan ti Ọlọrun fun wa ni ki a gbogun ti eṣu ti a ba ti kofiri pe o fẹ ba ẹbun ti Ọlọrun fun wa tabi oore ti Ọlọrun fun wa jẹ. A ti sọ eyi sẹyin pe eṣu le fi idibajẹ sinu agọ ara wa tabi sinu awọn ibaṣepọ wa, ki a ma ba gbadun wọn ati ki wọn ma ba wulo fun ete rere Ọlọrun. Ti a ko ba si fẹ ki eyi waye, a gbọdọ ma fi gbogbo igba duro ṣinṣin lati doju ija kọ ọ ati le danu kuro lọdọ wa
Ọna wo wa ni a le gba doju ija kọ eṣu, ki a si le danu kuro ninu aye wa? A le ṣe eleyi nipa gbigbe gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ. Pọọlu sọ wipe:
“Nitori naa, ẹ gbe gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ ki ẹyin ki o le dojukọ Eṣu ni ọjọ ibi, nigba ti ẹyin ba si ṣe ohun gbogbo tan, ki ẹ si duro. Ẹ fi amure otitọ di ẹgbẹ yin, ẹ si di igbaya ododo mọra; Ẹ si fi imura iyinrere alaafia wọ ẹsẹ yin ni bata; Leke gbogbo rẹ, ẹ mu apata igbagbọ, nipa eyi ti ẹyin o le ma fi pana gbogbo ọfa ina ẹni ibi naa. Ki ẹ si mu aṣibori igbala, ati ida Ẹmi, ti i ṣe ọrọ Ọlọrun. Pẹlu gbogbo adura ati ẹbẹ ni ki ẹ maa gbadura nigba gbogbo ninu Ẹmi, ki ẹ si maa ṣọra si i ninu iduro-ṣinṣin gbogbo, ati ẹbẹ fun gbogbo eniyan mimọ.” (Éfésù 6:13-18)
Njẹ o ri bayi? Ojuṣe wa ni lati gbe gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ, ki a ba le doju ija kọ eṣu nigbakugba ti a ba kẹfin rẹ. A si mẹnuba pataki lara awọn ihamọra wọnyi fun wa. A sọrọ nipa otitọ, ododo, iyinrere, igbagbọ, ọrọ Ọlọrun, oye igbala ati adura. Wayi, ọrọ pọ ti a le sọ lori bi a ti ṣe lo awọn nkan ti a mẹnuba yi gẹgẹ bi nkan ija lati doju ija kọ eṣu ati awọn ọmọ ogun rẹ. Amọ gbogbo awa ti a jẹ ọmọ Ọlọrun ni a gbọdọ lepa lati mọ nkan ti a kọ silẹ fun wa ninu bibeli lori iwuo awọn nkan yi lati doju ija kọ eṣu. Aijẹbẹ, a o ni ma ṣe amulo wọn bi o ti ṣe tọ ati bi o ti ṣe yẹ lati pa awọn nkan ti Ọlọrun fun wa mọ, ki idibajẹ ma ba de ba wọn.
EWU ÌDÍBÀJẸ́
Ewu wo ni o wa wa ninu ki idibajẹ de ba awọn nkan ti Ọlọrun fun wa? Akọkọ, o le mu ijiya lati ọwọ Ọlọrun lọwọ. Bi a ti ṣe ri ninu nkan ti a sọ nipa eṣu, ni kete ti idibajẹ de ba ọgbọn ati ẹwa rẹ ni Ọlọrun le kuro ni ipo ti o wa. Iyẹn jasi pe Ọlọrun doju ija kọ. Wo ọkan lara awọn ẹsẹ bibeli ti a ti sọ awọn nkan wọnyi lẹẹkan si:
““Ọkan rẹ gberaga nitori ẹwa rẹ. Iwọ si ba ọgbọn rẹ jẹ nitori didara rẹ. Nitori naa mo le ọ sori aye; mo si sọ ọ di awò oju niwaju awọn ọba.” (Ìsíkíẹ̀kì 28:17)
Ṣe o ri bayẹn? Ti a ba ti fi aye gba eṣu lati ba ohun yowu ti Ọlọrun fun wa gẹgẹ bi ẹbun jẹ, idajọ Ọlọrun le wa sori wa, ti a ko ba ṣaanu fun wa, ki a si le wa danu kuro nibi ti Ọlọrun fi wa si. Ranti pe a le Adamu ati Efa jade kuro ninu ọgba Edeni nigba ti wọn fi aye gba eṣu. Si tun ranti pe Ananaya ati aya rẹ Safira ku nitoripe idibajẹ wọ inu ififunni wọn. Adura mi ni pe a ko ni gbe igbesẹ kankan ti yoo jẹ ki Ọlọrun le wa danu kuro nibi ayọ ti O fi wa si. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 3; Ìṣe Àpọ́sítélì 5)
Ewu keji ti o sọrọ mọ ki a fi aye gba idibajẹ awọn ki Ọlọrun fun wa ni pe awọn nkan naa le ma wulo fun ete Ọlọrun mọ. Fun apẹrẹ, ti a ba fi aye gba idibajẹ ninu agọ ara wa, yala idibajẹ aisan ni tabi iṣekuṣe, agọ ara naa ko ni le wulo fun Ọlọrun bi o ti tọ ati yẹ. Eyi yoo si pa imuṣe ete rẹ ninu aye wa ati ninu aye awọn ti o wa ni awujọ wa lara.
Ewu ikẹta ni pe idibajẹ ko ni jẹ ki ohunkohun ti a ba fun Ọlọrun tabi ṣe fun un jẹ itẹwọgba. Ti ko ba si ti jẹ itẹwọgba, ko le si ere lori rẹ. O wa yẹ ki a mọ pe nkan ti a fun Ọlọrun le ma dibajẹ loju awọn eniyan. Ṣugbọn loju rẹ, o le ti dibajẹ, ki o si ma yẹ fun ere tabi iyin rẹ. (Wo: Lúùkù 16:15)
Fun apẹrẹ, Jesu sọ wipe ififunni aṣehan tabi adura agbahan ti dibajẹ niwaju Ọlọrun. Nitorina ko ni si ere fun wọn (Mátíù 6:1-6). Pọọlu pẹlu tun sọ fun wa pe ki a kiyesara lori ọna ti a n gba ṣiṣẹ fun Ọlọrun. Aijẹbẹ, iṣẹ wa yoo dibajẹ, yoo si jona, ko si tun ni si ere fun wọn (1Kọ́ríntì 3:10-15).
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Ni ipari, Ọlọrun ko da aye wa fun idibajẹ ṣugbọn fun iṣelogo rẹ. Nitorina, ojuṣe wa ni lati ṣe amulo oore-ọfẹ rẹ ati awọn ihamọra rẹ lati ma fi aye gba idibajẹ ninu aye wa tabi idibajẹ awọn nkan ti O fi fun wa tabi ṣe fun wa. Aijẹbẹ, igbe aye wa le di alailere niwaju rẹ tabi ki o di eyi ti idajọ rẹ yoo parun.
ÌBÉÈRÈ
– Bawo ni ẹkọ yi ṣe ran oye rẹ nipa igbe aye ti o tẹ Ọlọrun lọrun lọwọ?
Lati ọwọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2024 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07025105978)
ÀKỌ́RÍ: IPÓ ÀWỌN OBÌNRIN NÍNÚ ÌJỌ | ÀYỌKÀ: 1KỌRINTI 14:34-35 | ỌJỌ́RÚ 24, IGBE 2024
ÀKỌ́SÓRÍ: “Jẹ ki awọn obirin yin dakẹ ninu ijọ: nitori a ko fi fun wọn lati sọrọ, ṣugbọn jẹ ki wọn wa labẹ itẹriba, gẹgẹ bi ofin pẹlu ti wi.” (1Kọ́ríntì 14:34)
Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ
Oniruuru ẹkọ ni o ti jade lọ si aarin awọn ọmọ Ọlọrun ati sinu aye lori ipo awọn obirin ninu ijọ. O si wa ṣe ni laanu pe ọpọ awọn ẹkọ yi ti sọ ọpọ awọn obinrin ninu ijọ di ẹni ti ko fẹ nkankan ṣe ju ki wọn kan wa si ipade nigba ti o ba wu wọn, ki wọn da ọrẹ ti o ba ṣeeṣe, ki wọn si tun gba ile wọn lọ. Njẹ eyi wa ba ifẹ Ọlọrun fun awọn obinrin mu bi? Ki tilẹ ni bibeli sọ nipa ipo awọn obinrin ninu ijọ ati ipa ti wọn le ko? Awọn nkan wọnyi ni a fẹ gbe yẹwo ninu ẹkọ yi. Adura mi si ni pe ki Ẹmi Ọlọrun fi oye awọn nkan naa ye gbogbo wa ni ọna ti o peye, ki awọn obinrin wa ba a le gba aye ti Ọlọrun ti yan fun wọn pẹlu itara, ki awọn ọkunrin wa naa si ba le fi aye gba wọn ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun.
JẸ́ KÍ ÀWỌN OBIǸRIN YÍN DÁKẸ́ NÍNÚ ÌJỌ
Wayi o, ki a ba le mọ ipo ti Ọlọrun to awọn obinrin wa si ninu ijọ, a kọkọ gbọdọ ṣe agbeyẹwo awọn ẹṣẹ bibeli ti awọn oniwaasu ṣaba ma n lo lati to awọn obinrin ṣẹyin ninu ijọ. Pataki lara wọn si ni iwọnyi:
“Jẹ ki awọn obirin yin dakẹ ninu ijọ: nitori a ko fi fun wọn lati sọrọ, ṣugbọn jẹ ki wọn wa labẹ itẹriba, gẹgẹ bi ofin pẹlu ti wi. Bi wọn ba si fẹ kọ ohunkohun, ki wọn ki o beere lọwọ ọkọ wọn ni ile: nitori ohun itiju ni fun awọn obinrin lati maa sọrọ ninu ijọ.” (1Kọ́ríntì 14:34)
“Jẹ ki obinrin ki o maa fi idakẹjẹ ati itẹriba kọ ẹkọ. Ṣugbọn emi ko fi aṣẹ fun obinrin lati maa kọ awọn eniyan, tabi lati pasẹ lori ọkunrin, bi ko ṣe pe ki o dakẹjẹ. Nitori Adamu ni a kọ da, lẹyin naa, Efa. A ko si tan Adamu jẹ, ṣugbọn obinrin naa, nigba ti a tan an, o ṣubu sinu ẹṣẹ. Ṣugbọn a o gba obinrin la nipa ibimọ rẹ, bi wọn ba tẹsiwaju lati maa gbe ninu igbagbọ ati ifẹ ati iwa mimọ pẹlu iwa airekọja.” (1Tímótì 2:11-15)
Tani o kọ awọn nkan wọnyi silẹ fun wa ninu bibeli? Pọọlu ni. Nipasẹ ta si ni o fi kọ wọn? Nipasẹ Ẹmi mimọ ni. Nitorina, o ṣe pataki ki a tẹwọgba awọn nkan ti o sọ silẹ yi, ki a si ma bu ẹnu atẹ lu wọn. Aijẹbẹ, nṣe ni a o ma rin lodi si ifẹ Ọlọrun. Eyi si lewu fun wa ati fun awọn ti o ba n tẹle wa pẹlu. Amọ, o wa tun ṣe pataki ki a ma ṣi awọn nkan ti apọsiteli yi sọ silẹ tunmọ. Idi si ni wipe ṣiṣe eyi naa tun lewu fun wa pẹlu.
Ki wa ni o n sọ? Ki si ni ko sọ? Ti a ba mu awọn nkan ti o sọ silẹ yi lori, iduro ti a o duro ni pe obinrin ko ni ipo kankan pataki ninu ijọ ju pe ki o sa ma wa si ipade adura tabi ti ẹkọ bibeli lọ. Ṣe bẹẹ si ni o ri? Rara!
Ki wa ni idi ti Pọọlu fi sọ fun awọn ara Kọrinti ati fun Timoti pẹlu pe nṣe ni ki obinrin dakẹjẹ ninu ijọ, ki o ma si ṣe fọhun? Ti oye nkan ti o n sọ yoo ba ye wa, a kọkọ gbọdọ kiyesi koko nkan ti o n sọrọ le lori ninu awọn lẹta wọnyi? Koko nkan ti o si n sọrọ le lori ri ni eto ninu ijọ.
Ti a ba wo Kọrinti kinni, ori ikẹrinla daradara, fun apẹrẹ, a o ri wipe koko ọrọ Pọọlu nibẹ da lori ki a ma ṣe ohun gbogbo letoleto ati lẹsẹẹsẹ ninu ijọ. Ti a ba si tun wo ori keji iwe Timoti kinni pẹlu, a o ri wipe ọrọ lori awọn nkan ti o yẹ ki a ma ṣe ninu awọn ipade wa ni Pọọlu n ba Timoti sọ nibẹ. Fun apẹrẹ, o ba a sọrọ lori iha ti o yẹ ki a kọ si adura gbigba, paapaa julọ awọn ti o jẹ ọkunrin ijọ, ati awọn ti a nilo lati ma a gbadura fun, ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun. O si tun sọrọ lori bi o ti ṣe yẹ ki awọn obinrin onigbagbọ ma a mura ati pataki ki wọn ma fi iwa rere ṣe ara wọn ni ẹsọ. (Wo: 1Kọrinti 14:26-40; 1Tímótì 2:1-10)
Ki wa ni idi ti o fi sọ awọn nkan wọnyi? Idi ni ki idarudapọ ma ba a ma waye ninu ijọ. Ara awọn nkan ti o si le fa idarudapọ ninu ijọ ni ki awọn obinrin gbagbe aaye ti Ọlọrun to wọn si ninu ile wọn. Aye oluranlọwọ ni Ọlọrun to wọn si ninu ile, ko ki i ṣe aaye adari ile wọn. Ọkọ ni a to si aye oludari ninu ile kọọkan. Ti ile wa yoo ba si toro, ati ọkọ ati aya ni o gbọdọ tẹle alakalẹ yi. (Wo: Éfésù 5:22-33)
Nibakanna, ti ijọ yoo ba toro, a ko gbọdọ pa alakẹlẹ ti Ọlọrun fi lele fun wa ninu ile wa rẹ. A ko gbọdọ wipe nitoripe ko si iyatọ laarin ọkunrin ati obinrin ninu Kirisiti Jesu, ki awọn obinrin ma mọ iwọn ara wọn mọ ninu ijọ, ki wọn wa ma sọrọ si awọn ọkọ-ọlọkọ bi o ti ṣe wu wọn. Irufẹ nkan bayi le tu ijọ Ọlọrun. A si ti gbọ itan awọn ijọ kan ti o ti tu.
Idi wa niyi ti Pọọlu, nipasẹ ọgbọn Ẹmi mimọ ṣe sọ fun wa pe a gbọdọ fi han ninu gbogbo awọn ijọ wa pe awọn obirin wa ni itẹriba ni ile ọkọ wọn. Ọna kan pataki lati ṣe eleyi si ni kí á má fi wọ́n si ipo iṣedari lori awọn ọkunrin. Eyi ko ni fi aye silẹ fun awọn ọkunrin ati obinrin ti oye ọrọ Ọlọrun ko ye lati ri anfaani lati kẹgan ọrọ Ọlọrun. Ko si tun ni fi aye silẹ fun awọn obinrin ti ko ni ọgbọn iṣedari ti o ye kooro lati ṣi ipo wọn gẹgẹ bi adari lo ninu ijọ, ki wọn si silẹkun silẹ fun ikunsinu.´
Eyi ko wa jasi pe awọn obinrin ko ni anfaani lati sọrọ rara ninu ijọ tabi lati waasu. Wọn le sọrọ ninu ijọ. Wọn le bere ibere lori awọn nkan ti o ba ruju si wọn lori ifẹ Ọlọrun. Wọn si tun le waasu paapaa. Wo diẹ lara nkan ti bibeli sọ lori eyi:
“Bẹẹ naa ni obinrin ti o ba n gbadura tabi ti o ba n sọtẹlẹ laibo ori rẹ, ko bu ọla fun ori ara rẹ nitori ọkan naa ni pẹlu ẹni ti o fari.” (1Kọ́ríntì 11:3)
Ki ni ẹṣẹ bibeli yi fi ye wa? Oun naa ni pe awọn obinrin ni anfaani lati sọrọ ninu ijọ. Wọn ni anfaani lati gbadura ati lati sọtẹlẹ. A tilẹ tun ri ka ninu bibeli wipe Ajinyinrere Filipi ni asiko kan ni awọn ọmọbinrin mẹrin ti ko i ti lọkọ ti wọn n sọtẹlẹ (Ìṣe Àpọ́sítélì 21:8-9). Ki wa ni Ọlọrun n fun awọn obinrin ni ẹbun ifedefọ ati isọtẹlẹ si, ti ko ba fẹ ki wọn lo tabi ki wọn sọrọ ninu ijọ?
Ọlọrun ko lodi si ki awọn obinrin ma sọrọ ninu ijọ. Nkan ti Pọọlu kan n sọ fun wa ni pe ki a ma fi aye silẹ fun awọn obinrin ijọ lati ma fi oju rena awọn ọkọ wọn ati awọn ọkunrin miran ninu ijọ wọn, ki wọn si wa ma ṣe itọpinpin iṣẹ awọn adari ijọ wọn. Eyi ko bojumu rara. Eyi ko fihan pe awọn obinrin ti o n ṣe irufẹ nkan wọnyi bọwọ fun awọn ọkọ wọn. Ti wọn ba bọwọ fun wọn ni, nṣe ni wọn yoo lọ ba wọn lati bere ohunkohun ti ko ba ye wọn nipa nkan ti o n lọ ninu ijọ.
Ọrọ ti a n sọ yi ko tun jasi pe awọn obinrin ko le di ipo iṣedari kankan mu ninu ijọ. Wọn le di mu u. Niwọn igba ti Ọlọrun ba ti fun wọn ni ẹbun lati le kọ ni ati lati le ṣe amojuto awọn eniyan tabi lati le ṣe amojuto awọn nkankan ti o jẹ ti ijọ, a ko gbọdọ di wọn lọwọ lati lo awọn ẹbun yi. Eyi ko si ni nkankan ṣe pẹlu pe ki wọn jẹ gaba lori awọn ọkunrin ijọ tabi pe ki wọn ma pa aṣẹ fun wọn. Wọn le ma ṣe akoso awọn obinrin ẹgbẹ wọn, fun apẹrẹ. Wọn si tun le ma ṣe akoṣo awọn ọmọde inu ijọ tabi awọn ọdọmọkurin ati ọdọmọbinrin inu ijọ, ni ibamu pẹlu oore-ọfẹ ti a fi fun wọn. Yatọ si eyi, ti wọn ba ni ẹkọ, imọ ati oye ti o peye lori ofin, eto iṣuna, ile kikọ ati bẹẹ bẹẹ lọ, wọn le ṣe amojuto awọn nkan wọnyi fun ijọ wọn.
Idi ni yi ti Pọọlu fi sọ fun Timoti ninu lẹta rẹ pe o le fi awọn obinrin ti o ba n ṣe deede, ti o si tun ja fafa ninu ijọ naa ṣe diakoni (1Tímótì 3:11). A si ri awọn apẹrẹ awọn obinrin ti a mọ si diakoni ninu bibeli, ti wọn si ṣiṣẹ takuntakun fun awọn ijọ wọn (Roomu 16). Nitorina, aṣitumọ ọrọ Ọlọrun ni yoo jẹ ki a fi ọwọ rọ awọn obinrin ṣẹyin ninu awọn ijọ wa. Ipa ti Ọlọrun fẹ ki wọn ma ko ninu ijọ ga, bi a o ti ṣe tun ri ninu ẹkọ yi. Nkan ti Ọlọrun ko kan fi aye silẹ fun ni rudurudu ati isọrọ-odi ti o le tipasẹ ki a fi awọn obinrin ṣe alakoso le awọn ọkunrin lori ninu ijọ.
OBIǸRIN LE ṢÀKÓṢO ÌJỌ
Amọ ṣa o, ti a ba wa ri ibi ti obinrin ti ni oye ju awọn ọkunrin lọ nkọ, ti Ọlọrun si fun ni ẹbun iṣedari ati itọni pẹlu, njẹ yoo lodi si ifẹ Ọlọrun lati fi aaye gba irufẹ obinrin bẹ ẹ lati ma kọni ninu ijọ ati lati ma mojuto awọn ọmọ Ọlọrun? Ko ni lodi si ifẹ Ọlọrun. A si ri apẹrẹ eyi ninu Debora igba aye bibeli. O jẹ ọkan lara awọn onidajọ ti orilẹ-ede Israẹli ni ki wọn to bẹrẹ si ni jọba. A tilẹ ri wipe Baraki gan, ti Ọlọrun lo lati gba orilẹ-ede yi silẹ ko ṣetan lati gbe igbesẹ akin kankan ti Debora ko ba ṣetan lati duro ti i gbagba. (Wo: Onídájọ́ 4-5)
A tun ri apẹrẹ Prisila, aya Akuila, ninu bibeli. A ri wipe gbogbo ibi ti Pọọlu ba ti tọka si ọkọ rẹ gẹgẹ bi alabaṣiṣẹ pọ rẹ ninu iṣẹ Kirisiti Jesu ni o ti n tọka si oun naa pẹlu gẹgẹ bi alabaṣiṣẹpọ rẹ ninu iṣẹ iyinrere. A tun ri wipe gbogbo ibi ti o ba ti mẹnuba ijọ Ọlọrun ti o wa ni ile awọn tọkọtaya yi naa ni o ti ma n mẹnuba orukọ awọn mejeji gẹgẹ bi adari ijọ yi. A si tun ri wipe awọn mejeji yi ni Ọlọrun lo lati kọkọ fi imọ iyinrere Jesu ye Apọsiteli Apolo daradara. (Wo: Ìṣe Àpọ́sítélì 18:24-26; Róòmù 16:3; 1Kọ́ríntì 16:19; 2Tímótì 4:19)
Nitorina, ko si ibi ti a kọ si ninu bibeli pe oye ọrọ Ọlọrun ko le ye awọn obinrin ijọ bi o ti ṣe ye awọn ọkunrin ijọ tabi jubẹ lọ gan paapaa. Ko si si ibi ti a kọ si ninu bibeli pe awọn obinrin ko le ni awọn ẹbun Ẹmi mimọ kan ti awọn ọkunrin le e ni. Ibikibi ti awọn ọkunrin ijọ ko ba si ti duro ni ipo wọn gẹgẹ bi adari nipa ti ẹmi, ti a si ri obinrin ti oye nkan ẹmi ye ju wọn lọ nibẹ, ko ni lodi si ifẹ Ọlọrun ki obinrin naa bọ si ipo adari nipa ti ẹmi laarin wọn. Ara nkan ti yoo si jẹ ki a mọ pe Ọlọrun fi aṣẹ si ni pe awọn ti o jẹ ọkunrin nibẹ yoo tẹwọgba iṣedari irufẹ obinrin bẹ ẹ, bi Baraki ati awọn ọkunrin orilẹ-ede Isiraẹli igbaani ti ṣe tẹwọgba iṣedari Debora.
Ọ̀KAN NI WỌ́N NÍNÚ KÍRÍSÍTÌ
Ki a wa ma gbagbe pe bibeli sọ awọn nkan wọnyi fun wa nipa ipo ati ọkunrin ati obinrin ninu ijọba Ọlọrun:
“Jesu si dahun o wi fun wọn pe, Ki i ha ṣe nitori eyi ni ẹ ṣe ṣina, pe ẹyin ko mọ iwe-mimọ tabi agbara Ọlọrun? Nitori nigba ti wọn o jinde kuro ninu oku, wọn ko ni gbeyawo bẹẹ ni wọn ki yoo si ni ni iyawo; ṣugbọn wọn yoo dabi awọn angẹli ti n bẹ ni ọrun.” (Máàkù 12:24-25)
“Ṣugbọn ọkunrin ki le ṣe laisi obinrin, bẹẹ ni obinrin ko le ṣe laisi ọkunrin ninu Oluwa.” (1Kọrinti 11:11)
“Nitori pe ọmọ Ọlọrun ẹyin n ṣe, nipa igbagbọ ninu Kirisiti Jesu. Nitori pe iyẹ ẹyin ti a ti bapitisi sinu Kirisiti, ti gbe Kirisiti wọ. Ko le si Juu tabi Heleni, ẹru tabi ominira, ọkunrin tabi obinrin: nitori pe, ọkan ni gbogbo yin jẹ ninu Kirisiti Jesu.” (Gàlátíà 3:26-28)
“Bẹẹ gẹgẹ ẹyin ọkọ, ẹ maa fi oye ba awọn aya yin gbe, ki ẹ si maa bu ọla fun wọn gẹgẹ bi ohun elo ti ko lagbara, ati pẹlu bii ajumọ-jogun oore-ọfẹ iye: ki adura yin ki o ma baa ni idena.” (1Pétérù 3:7)
Nkan ti awọn ẹṣẹ bibeli yi n fi idi rẹ mulẹ fun wa nipe ọkunrin ko ṣe pataki ju obinrin lọ ninu ijọba Ọlọrun. Iha ti olokuluku ba kọ si ijọsin Ọlọrun ni yoo sọ bi Ọlọrun yoo ti ṣe fi ara rẹ han to ati bi yoo ti ṣe lo onitọun to. Yatọ si eyi, wọn tun n jẹ ki o ye wa pe ni aye yi nikan ni ọkunrin ti ni anfaani lati wa ni ipo adari lori obinrin, iyẹn ninu ile ati ninu ijọ. Ni ijọba Ọlọrun ko ni si nkan ti o n jẹ obinrin – bi angẹli ni gbogbo wa yoo ti ṣe ri.
IṢẸ́ OBIǸRIN NÍNÚ ÌJỌ
Wayi o, wipe gbèdéke wa lori anfaani ti obinrin ni lati wa ni ipo adari ninu ijọ ko tunmọ si pe ko si iṣẹ kankan fun lati ṣe. Oniruuru iṣẹ ni Ọlọrun fẹ ki awọn obinrin ma a ṣe ninu ijọ wọn ati fun ijọba ọrun. Diẹ lara awọn iṣẹ yi si ni iwọnyi:
Ìpolongo ìyìnrere
Tani ẹni ti o kọkọ ri Jesu lẹyin ajinde rẹ? Obinrin ni. Tani o kọkọ lọ sọ fun awọn ọmọ ẹyin pe Jesu ti ji dide? Obinrin ni. Nitorina, obinrin ni ipa ti o pọ lati ko ninu ki a polongo iyinrere. A tilẹ ri apẹrẹ arabinrin Samaria kan ninu bibeli, ti o mu iyin nipa Jesu lọ sinu ilu rẹ, ti o si ko gbogbo awọn ara ilu naa wa sọdọ Jesu lati gbọ ọrọ rẹ. (Wo: Jòhánù 4 &20).
Nitorina, iṣẹ ijinyinrere ko ki i ṣe fun awọn ọkunrin ijọ nikan. O wa fun awọn obinrin naa pẹlu. Ki a tilẹ sọ otitọ, o fẹrẹ rọrun fun awọn obinrin lati jiyinrere ju awọn ọkunrin lo nitori iṣẹda wọn. Bibeli si wa tun sọ eyi fun wa: “Oluwa ti paṣẹ ọrọ, pupọ ni ogun awọn ẹni ti o n royin rẹ.” (Sáàmù 68:11) Ti a ba ka ẹsẹ bibeli yi kanna lati inu bibeli ti ede Heberu, a o ri wipe obinrin ni awọn ti a tọka si gẹgẹ bi ‘ẹni ti o n royin’ ninu ẹsẹ bibeli naa.
Eyi n jẹ ki o ye wa pe ifẹ Ọlọrun ni ki awọn obinrin wa ninu ijọ ma fi ara wọn jin lati polongo iyinrere Kirisiti Jesu nibikibi ti wọn ba wa, pẹlu ọrọ, iwa ati iṣe wọn. Ki a si wa sọ otitọ, ijọ ti awọn obinrin rẹ ko ba ti fi ara wọn jin fun ipolongo iyinrere le ma pọ si ni ilọpo-ilọpo pẹlu oniruuru eniyan bi o ti ṣe tọ ati bi o ti ṣe yẹ.
Ìfifúnni fún iṣẹ́ ìránṣẹ́
Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, awọn obinrin ni o ṣe agbatẹru iṣẹ iranṣẹ Jesu ju nigba aye rẹ. Iwọ naa wo awọn ẹsẹ bibeli yi:
“Ọpọ obinrin ti o wa lati Galili pẹlu Jesu lati tọju rẹ wọn n wo o lati okeere. Ninu awọn obinrin ti o wa ibẹ ni Maria Magidaleni, ati Maria iya Jakọbu ati Josẹfu, ati iya awọn ọmọ Sebede mejeeji wa nibẹ pẹlu.” (Mátíù 27:55-56)
“Lẹyin naa ti o la gbogbo ilu ati ileto kọja, o n waasu, o n ro iyin ayọ ijọba Ọlọrun: awọn mejila naa si n bẹ lọdọ rẹ. Ati awọn obinrin kan, ti o ti mu larada kuro lọwọ awọn ẹmi buburu, ati ninu ailere wọn: Maria ti a n pe ni Magidaleni, lara ẹni ti ẹmi Eṣu meje ti jade kuro, ati Jona aye Kusa ti i ṣe iriju Hẹrọdu, ati Susana, ati awọn pupọ miran, ti wọn n ṣe iranṣẹ fun un ninu ohun ini wọn.” (Luuku 6:1-3)
Njẹ o ri bayẹn pe bi o tilẹ jẹ wipe awọn ọlọrọ wa ni ilu daradara nigba ti Jesu wa laye, ti O si n waasu, a ko sọ wipe awọn ọlọrọ kan ni wọn n ṣe iransẹ fun pẹlu ini wọn. Dipo eyi, a sọ wipe awọn obinrin kan ni wọn n ṣe iranṣẹ fun ninu ini wọn. A si tun ri wipe, nigba ti Pọọlu de ilu Filipi, arabinrin kan ti a n pe ni Lidia, ti o n ta aṣọ eleṣe aluko, ni o gba oun ati awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ sile, ti o si n tọju wọn pẹlu nkan ini rẹ ni gbogbo igba ti wọn fi wa ni ilu yi (Ìṣe Àpọ́sítélì 16:11-15).
Ki ni eyi n fi ye wa? Oun naa ni pe awọn obinrin ni ipa ti o pọ lati ko ni riran iṣẹ iranṣẹ awọn oniwaasu lọwọ pẹlu nkan ini wọn. Ranti opo Ṣarefati. Si ranti arabinrin Ṣunemu naa. Obinrin ni awọn mejeji yi. Ọlọrun si lo wọn lọpọlọpọ lati ran awọn iransẹ rẹ lọwọ. Nitorina, ti a ba ri ijọ ti o n fa sẹyin ni titọju awọn ojiṣẹ Ọlọrun ati riran iṣẹ iranṣẹ wọn lọwọ, a jẹ wipe awọn obinrin ibẹ ya ahun ni yẹn. Bẹẹni, a jẹ wipe oju awọn obinrin ijọ naa ko i ti ṣi si iṣẹ iranṣẹ wọn lati ma ran awọn oniwaasu wọn lọwọ pẹlu nkan ini wọn niyẹn. (Wo: 1Àwọn Ọba 17; 2Àwọn Ọba 4)
Ti oju awọn obinrin ijọ wa ba ṣi si ki wọn ma ran iṣẹ iranṣẹ awọn adari wọn lọwọ pẹlu nkan ini wọn, bi awọn ọkọ wọn tilẹ fẹ ya ahun, wọn yoo wa ọna lati ṣe nkan ti o tọ. Ranti Abigẹli ati Nabali. Nabali ya ahun nitootọ. Sibẹsibẹ, Abigẹli wa ọna lati ṣe nkan ti o tọ, ki idile rẹ ma ba parun. Nitorina, ti idile rẹ, gẹgẹ bi obinrin, ko ba ki fifunni lọna ti o peye, a jẹ wipe ahun ni ọ. Eyi ko si le jẹ ki Ọlọrun ri ọ lo bi o ti ri awọn obinrin ti a mẹnuba ṣẹyin yẹn lo. (Wo: 1Sámúẹ́lì 25)
Fífi ìdí àṣà tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run lélẹ̀ fún àwọn ọmọdé àti ọ̀dọ́bìnrin
Yatọ si awọn nkan ti a ti mẹnuba ṣiwaju, ọkan pataki miran lara ojuṣe awọn obinrin ijọ ni ki wọn ma fi idi awọn aṣa ti o wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun lọlẹ ni aarin ijọ. Lọna wo? Akọkọ, nipa fifi ara wọn jin lati kọ ẹkọ ọrọ Ọlọrun. Ekeji, nipa fifi ara wọn jin fun iṣẹ rere ati imura ti o tọna lati le jẹ awokọsẹ rere fun awọn ti o n tẹle wọn, iyẹn awọn ọmọde ijọ ati awọn ọdọbinrin ijọ. Ẹkẹta, nipa fifi aye silẹ lati ma kọ awọn ti o wa lẹyin wọn ni ifẹ Ọlọrun.
Iwọ naa wo nkan ti Pọọlu sọ fun Titu lori eyi:
“Bakan naa, ni ki o kọ awọn agba obinrin lẹkọọ lati kọ bi aati gbe igbe-aye ẹni-ọwọ, wọn ko gbọdọ jẹ afọrọ-kẹlẹ-ba-tẹni-jẹ tabi olufẹ waini mimu, ṣugbọn wọn gbọdọ jẹ olukọ ohun rere. Nipa eyi, wọn yoo le maa kọ awọn ọdọbinrin lati nifẹẹ awọn ọkọ wọn ati awọn ọmọ wọn, lati jẹ ẹni iwọntunwọnsi ati ọlọkan mimọ, ki wọn maa ṣe ojuṣe wọn ninu ile, wọn gbọdọ jẹ oninu rere, ki wọn si maa tẹriba fun awọn ọkọ wọn, ki ẹnikẹni maa baa sọrọ odi si ọrọ Ọlọrunn.” (Títù 2:3-5)
Njẹ o ri bayẹn pe iṣẹ pọ fun awọn obinrin ijọ? Ko ki i ṣe ojuṣe awọn alufa wa nikan ni lati ma kọ awọn ọmọbinrin wa ni iwa ti o tọ lati wu lawujọ ati ni ile wọn. Ojuṣe awọn obinrin ijọ, paapaa julọ awọn ti o ti dagba diẹ lara wọn, ni lati ma ṣe eyi pẹlu. A si ti mẹnuba ọna ti wọn yoo gba lati le ṣe e. Ti wọn ba wa mura si iṣẹ wọn, yoo farahan ninu iwa ati iṣe awọn ọdọbinrin ati awọn ọmọde inu ijọ wa. Ti wọn ko ba si mura si iṣẹ yi, yoo farahan pẹlu. Ṣugbọn oye gbọdọ ye wọn pe o ni ibi ti awọn alufa ijọ ati awọn adari ijọ miran ti o jẹ ọkunrin le ba awọn ti o jẹ ọdọbinrin sọrọ mọn tabi ba wọn lo pọ mọn. Ti awọn ti o jẹ obinrin bi ti wọn ko ba fi ara wọn jin lati ran wọn lọwọ ati lati fi idi aṣa ati iṣe ti o wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun mulẹ fun wọn, ko si ni ki iṣekuṣe ma fẹrẹ gbode kan ninu irufẹ ijọ bẹẹ. Apẹrẹ si pọ jantirẹrẹ.
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Ni akotan, nkan ti a n sọ ni pe awọn obinrin wa ninu ijọ ko ki i ṣe ẹni afọwọrọsẹyin. Bi awọn ọkunrin ti ṣe wulo niwaju Ọlọrun ni awọn naa wulo pẹlu. Bi o tilẹ wa jẹ wipe ọkunrin ni Ọlọrun to si ipo adari ninu ile ati ninu ijọ, ko jasi pe ko le lo awọn obinrin ti o ba gbamuṣe naa nibi ti ko ba ti si ọkunrin ti o koju-osuwọn iṣedari ati itọni ninu ijọ. Ko si tun jasi pe Ọlọrun ko ni alakalẹ oniruuru ipa ti awọn obinrin le ma ko ninu ijọ ati fun igberusi ijọba rẹ. Nṣe ni a nilo lati bẹrẹ si ni kọ awọn obinrin wa lati sọji si ohun yowu ti Ọlọrun ba fẹ ẹ lo wọn fun ninu ijọba rẹ, ki a si tun kọ awọn ọkunrin wa lati fi aye gba wọn ni ibamu pẹlu oore-ọfẹ ti Ọlọrun ba fun ẹnikọọkan wọn.
ÌBÉÈRÈ
– Bawo ni ẹkọ yi ṣe ran oye rẹ lori ipo awọn obinrin ninu ijọ lọwọ si?
Láti ọwọ́ Johnson O. Lawal
Copyright © 2024 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07025105978)
ÀKỌ́RÍ: 1PÉTÉRÙ 4 – ÌJÌYÀ BÍ KÌRÌSÌTÍẸ́NÌ | ÀYỌKÀ: 1PÉTÉRÙ 4:1-22
ÀKỌ́SÓRÍ: “Nitori naa, ẹ jẹ ki awọn ti n jiya gẹgẹ bi ifẹ Ọlọrun, fi ọkan wọn le Ẹlẹdaa oloootọ lọwọ pẹlu ni rere ṣe.” (1Pétérù 4:19)
Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ
Ninu ẹkọ ti a kọ kẹyin ninu lẹta Peteru akọkọ, a ri pe o ṣe pataki ki awa ti a pe ara wa ni onigbagbọ ninu Kirisiti Jesu ya a sọtọ ninu ọkan wa gẹgẹ bi Oluwa wa. Eyi jasi pe a gbọdọ ma fi gbogbo igba rin pẹlu afiyesi pe awa kọ ni oludari aye wa – Jesu ni. Nitorina, nkan ti O ba pa laṣẹ fun wa ni a gbọdọ tẹle. A ko lẹtọ mọ lati ma ṣe ifẹ inu wa. Eyi wa kọja ọrọ ẹnu. Igbe aye Kirisitiẹni kọja afẹnujẹwọ. O gbọdọ farahan ninu iṣeṣi wam ninu ile wa ati laarin awujọ wa pe Jesu ni Oluwa wa nitootọ. Aijẹbẹ, nṣe ni a kan n tan ara wa jẹ. (Wo: 1Pétérù 3:1-16)
ÌJÌYÀ BÍ I KÌRÌSÌTÌẸ́NÌ
Amọ ṣa o, bi Peteru tun ti ṣe fi ye wa, wipe a wa n gbe igbe aye Kirisitiẹni tootọ ko tunmọ si pe awọn eniyan yoo ma fi igba gbogbo fi ojurere wo wa. Wọn le ma fi ojurere wo wa rara. Wọn tilẹ le ma tabuku wa, ki wọn tun ma ṣe inunibini si wa. Idi si ni pe oye ko ye wọn. Iha wo wa ni o yẹ ki a kọ si eyi? Idahun Peteru ninu ori kẹta lẹta yi fi ye wa pe iha ti Jesu Oluwa wa naa kọ si inunibini awọn eniyan ni awọn naa gbọdọ kọ si. A wa gbọdọ ranti pe Jesu ko jiya nitoripe ẹlẹṣẹ ni. Dipo eyi, nṣe ni o jiya gẹgẹ bi arọpo fun awọn ẹlẹṣẹ. O si jiya lọna yi nitoripe ifẹ Ọlọrun ni fun un lati ṣe bẹẹ, ki igbala ba le tọ gbogbo iran eniyan wa. Lẹyin ti O si ti ṣe eyi tan, Ọlọrun gbe soke lati di alaṣẹ lori gbogbo ẹda rẹ. (Wo: 1Pétérù 3:17-22)
Nibakanna, ti a ba nilo lati jẹ iya lọnakan tabi omiran, o gbọdọ jẹ wipe o wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun. Eyi jasi pe ijiya wa gbọdọ jẹ eyi ti o n ṣiṣẹ lati mu ifẹ Ọlọrun ṣẹ. Lọna wo? Akọkọ, ijiya wa ko gbọdọ jẹ ijiya fun ẹṣẹ. Ẹni ti o ba n jiya fun ẹṣẹ ti o da ko gbọdọ sọ wipe oun jiya lati mu ifẹ Ọlọrun ṣẹ. Ekeji, ijiya wa ko gbọdọ jẹ ijiya fun aimọkanmọkan wa. Ẹkẹta, ijiya wa ko gbọdọ jẹ ijiya ti o sọrọ mọ aiṣe amulo ipese Ọlọrun fun wa.
Awọn nkan wọnyi ni Peteru fẹ ki a fi sọkan ti a ba n sọrọ lori ijiya gẹgẹ bi Kirisitiẹni ti o fi sọ fun wa pe, “Nitori o san, bi o ba jẹ ifẹ Ọlọrun, ki ẹ jiya fun ṣiṣe rere ju fun ṣiṣe buburu lọ.” (1Pétérù 3:17) Ṣe iwọ naa ri wipe o sọ pe ‘Bi o ba jẹ ifẹ Ọlọrun’. Eyi jasi pe ko ki i ṣe gbogbo igba naa ni Ọlọrun ma n fẹ ki awọn ọmọ rẹ jiya tabi la awọn iṣoro kan kọja nitori orukọ Jesu. Nitorina, ki a to le sọ wipe ijiya kan wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun, a gbọdọ ri daju pe ko ki i ṣe afọwọfa.
Ọrọ yi tun wa ni Peteru tẹsiwaju lati salaye siwaju si ni ori kẹrin lẹta yi, eyi ti a fẹ ṣe agbeyẹwo rẹ ninu ẹkọ yi. O si bẹrẹ nipa pipe akiyesi wa lẹkansi si iha ti Jesu kọ si ijiya fun ẹṣẹ wa ati pataki ki awa naa kọ iha kanna si ijiya aitọ. Wo nkan ti o sọ:
“Njẹ bi Kirisiti ti jiya fun wa nipa ti ara, iru ero kan naa ni ki ẹyin ki o fi mu ara yin ni ọkan le: nitori ẹni naa ti o ti jiya nipa ti ara, o ti bọ lọwọ ẹṣẹ. Ki oun ki o ma baa gbe igbe aye rẹ yooku ninu ara gẹgẹ bi ifẹkufẹẹ eniyan, bi ko ṣe bi ifẹ Ọlọrun. Nitori ti ẹyin ṣaa ti fi akoko wọn-ọn-ni ṣe gẹgẹ bi awọn keferi, bii iwa wọbia, ifẹkufẹẹ, on amùpara, irede oru, kiko ẹgbẹ ọmuti ati ibọriṣa ti i ṣe ohun irira. Eyi ti o n ya wọn lẹnu pe ẹyin ko darupọ mọ wọn lati ṣe iru aṣeju iwa wọbia wọn, ti wọn si n sọrọ yin ni buburu. Awọn ẹni ti yoo jiyin iṣẹ wọn fun Ọlọrun, ẹni ti yoo ṣe idajọ awọn alaaye ati oku. Nitori eyi ni a ṣaa ṣe waasu iyinrere fun awọn oku, ki a le ṣe idajọ wọn gẹgẹ bi eniyan nipa ti ara, ṣugbọn ki wọn ki o le wa laaye si Ọlọrun nipa ti ẹmi.” (1Pétérù 4:1-6)
Ki ni nkan akọkọ ti Peteru fẹ ki o ye wa ninu akọsilẹ rẹ yi? Oun naa ni pe ẹni ti ẹṣẹ ko ba ni ni ipa lori rẹ gbọdọ ṣetan lati jiya ninu ara bi Jesu ti ṣe jẹ iya ninu ara fun ẹṣẹ wa. Jesu ko dẹṣẹ rara. Sibẹsibẹ, O fi ara rẹ jin fun iya nitori ki O ba le san gbese ẹṣẹ wa. Awa naa wa gbọdọ fi oye yi gbaradi ninu ọkan wa lati fi ara wa jin fun iya, ti o ba jẹ wipe eyi ni ko ni jẹ ki a dẹsẹ si Ọlọrun. Ẹni ti ko ba si ṣetan lati ṣe eyi, lẹyin igba ti o ti tọ Jesu wa, ko ti ṣetan lati rin ni iṣẹgun lori gbogbo ẹṣẹ. Amọ ẹnikẹni ti o ba ṣetan lati ṣe yi n fihan pe oun ti bọ nitootọ kuro lọwọ ẹṣẹ.
Peteru wa tẹsiwaju lati jẹ ki o ye wa pe asiko ti a ti lo lati dẹṣẹ gan ti to. Eyi ti o tunmọ si pe ẹṣẹ ti a ti da ti o gẹẹ. Ti a ko ba da omiran mọ gan – eyi ti a ti da sẹyin ti ba aye wa ati ti awọn miran jẹ to. Nitorina, bi o tilẹ ṣe ajeji si awọn ti a jọ n jumọ dẹṣẹ tẹlẹ pe a ko kopa mọ ninu awọn iwa eeri ti a jọ n wu, ko gbọdọ ṣe ajoji si awa. Ko gbọdọ ṣe ajoji si wa nitoripe oye ti ye wa pe Ọlọrun yoo ṣe idajọ gbogbo eniyan, ati oku ati alaaye, ni ọjọ kan. Bẹẹni, ẹnikọọkan yoo jiyin bi o ti se lo aye rẹ fun Ọlọrun ni ọjọ idajọ. Bawo wa ni Ọlọrun ṣe fẹ ṣe idajọ awọn oku? Yoo ṣe idajọ wa ni ibamu pẹlu bi wọn ti ṣe lo aye wọn ninu ara. Awọn ti o ba si wa gba iyinrere rẹ gbọ nigba ti wọn wa laye, ti wọn si gbe aye wọn ni ibamu rẹ, yoo waa laaye pẹlu Ọlọrun nipa ti ẹmi titi lailai.
Ọjọ wo wa ni ọjọ idajọ ti a n sọ yi? Ko si ẹni ti o mọ. Amọ Peteru jẹ ki o ye wa ninu abala lẹta rẹ ti a n wo yi pe opin ohun gbogbo ti de naa. Ṣe eyi wa le jẹ otitọ bi, ti a ba fiyesi pe o kọ awọn ọrọ wọnyi silẹ niwọn bi okoolelẹgbẹrun ọdun meji sẹyin? Otitọ ni. Otitọ ni nitoripe a fi ye wa ninu bibeli pe ọjọ kan dabi ẹgbẹrun ọdun niwaju Ọlọrun ati ẹgbẹrun ọdun bi ọjọ kan niwaju rẹ. Nitorina igba ikẹyin ni a wa yi, eyi ti o tunmọ si pe oni oloni yi le jẹ ọjọ idajọ Ọlọrun ti a n reti.
Niwọn igba ti eyi si ribẹ, bi o ti wu ki igba ati asiko ti a ba ara wa ninu rẹ ri, awa ti a jẹ ọmọ Ọlọrun ko gbọdọ gbagbe ara wa lori pe a fẹ ni ọrọ, ni ọla tabi di gbajumọ, bi o tilẹ jẹ wipe ko si nkan ti o buru lati ni awọn nkan wọnyi lọna ti o tọ. Aijẹbẹ, a ko ni le fi ara wa jin fun adura gbigba, iyẹn fifi igbẹkẹle wa sinu Ọlọrun, ati iṣẹ rere ṣiṣe. Nitorina, Peteru sọ fun wa pe:
“Ṣugbọn opin ohun gbogbo fẹrẹ de: nitori naa ki ẹyin ki o ko ara yi ni ijanu, ki ẹ si maa ṣọra ninu adura. Ju gbogbo rẹ lọ, ẹ fẹran ara yin gidigidi: nitori ifẹ ni n bo ọpọlọpọ ẹṣẹ mọlẹ. Ẹ maa ṣe ara yin ni alejo laisi ikunsinu. Bi olukuluku ti ri ẹbun gba, bẹẹ ni ki ẹ maa ṣe ipinfunni rẹ laarin ara yin, bi iriju rere ti oniruuru oore-ọfẹ Ọlọrun.” (1Pétérù 4:7-10)
Njẹ o ri bayi? Ipokipo ti a le wa, a gbọdọ ma fi igba gbogbo ko ara wa ni ijanu, gbadura ati ṣe iṣẹ rere nipa fififunni ati lilo ẹbun ẹmi yowu ti Ọlọrun fun wa fun igbero awọn ara wa ninu Kirisiti. Pe a wa n ṣe awọn nkan wọnyi, bi a ti ṣe sọ tẹlẹ, ko tunmọ si pe a ko ni ba inunibini ati oniruuru ijiya pade nitori igbagbọ wa ninu Jesu. Awọn ọmọ Ọlọrun igbaani naa ba wọn pade, gẹgẹ bi Peteru ti ṣe fi han wa ninu lẹta yi. Awa naa si gbọdọ mura lati ba wọn pade ati lati mọ iha ti o tọ lati kọ si irufẹ inunibini tabi ijiya yowu ti a le ba pade gẹgẹ bi Kirisitiẹni. A si ti sọ fun wa sẹyin pe iha ti Jesu kọ si wọn ni awa naa gbọdọ kọ si wọn.
Iha wo ni O kọ si wọn? O tẹwọ gba wọn lailai kun sinu tabi sọ ọrọ odi. Ti awa naa ba si ba ara wa ni ipo ti Jesu ti ba ara rẹ nigbanaa tabi eyi ti o fara pẹ ẹ, a ko gbọdọ kun sinu tabi sọ ọrọ odi si ẹnikẹni. Eyi ni Ọlọrun yoo fi le lo ijiya wa fun itẹsiwaju iṣẹ rẹ laarin awọn eniyan.
Iyẹn nikan wa ko ni o. Bi Peteru tun ṣe fi ye wa ninu lẹta yi, a tun nilo lati kun fun ayọ ni asiko ti a ba n jiya nitori Jesu. Irufẹ ayọ wo ni a si n sọrọ nipa? Ayọ wipe a jẹ alabapin iya Kirisiti! Eyi ti o tunmọ si pe irufẹ ijiya yi ko ni lọ lasan – Ọlọrun yoo san wa ni ẹṣan fun un nigba ti ogo rẹ ba farahan. Amọ ṣa o, Peteru tun tẹnumọ fun wa pe ijiya bi i Kirisitiẹni gbọdọ jẹ eyi ti o sorọ mọ inunibini nitori pe a n tẹle Jesu. Aijẹbẹ, a kan n jiya lasan ni, yatọ si pe a le tun ma ko ẹrẹ̀ ba orukọ Jesu. Iwọ naa wo nkan ti o sọ:
“Olufẹ, ẹ maa ṣe ka idanwo bi ina eyi ti a fi n dan yin wo bi ẹni pe ohun ajeji ni o de baa yin. Ṣugbọn niwọn bi ẹyin ti jẹ alabapin iya Kirisiti, ẹ maa yọ, ki ẹyin ki o lee yọ ayọ pupọ nigba ti a ba fi ogo rẹ han. Bi a ba n gan yin nitori orukọ Kirisiti, ẹni ibukun ni yin; nitori Ẹmi ogo ati ti Ọlọrun ba le yin: nipa tiwọn wọn n sọrọ rẹ ni ibi, ṣugbọn nipa tiyin, a yin in logo. Ṣugbọn ẹ ma ṣe jẹ ki ẹnikẹni ninu yin ki o jiya bi apaniyan, tabi bi ole, tabi bi oluṣe-buburu, tabi bi ẹni ti n tojubọ ọran elomiran. Ṣugbọn bi iwọ ba jiya bi Kirisitiẹni, ma ṣe tiju; ṣugbọn ki o kuku yin Ọlọrun logo ninu orukọ yii.” (1Pétérù 4:12-16)
Njẹ o ri bayẹn? Niwọn igba ti o ba jẹ nitori Kirisiti ni a ṣe n jiya, a ko gbọdọ tiju tabi kanra. Dipo eyi, nṣe ni o yẹ ki a kun fun ayọ, ki a si tun ma fi ogo fun Ọlọrun. Idi si ni pe ayọ wa yoo pada wa di ẹkunrẹrẹ.
Peteru wa pari ọrọ rẹ lori ijiya bi Kirisitiẹni nipa jijẹ ki o ye wa pe idajọ Ọlọrun tilẹ ti bẹrẹ – awọn eniyan ko kan mọ ni. Lọna wo? Nipa ṣiṣe afọmọ ile rẹ ni! Wo bi Peteru ti ṣe gbe ọrọ naa kalẹ:
“Nitori ti akoko naa de, ti idajọ yoo bẹrẹ lati ile Ọlọrun wa: bi o ba si tete ti ọdọ wa bẹrẹ, opin awọn ti ko gba iyinrere Ọlọrun gbọ yoo ha ti ri? Bi o ba ṣe pe agbara kaka ni a fi gba olododo la nibo ni alaiwa-bi-Ọlọrun ati ẹlẹṣẹ yoo gbe yọju si? Nitori naa ẹ jẹ ki awọn ti n jiya gẹgẹ bi ifẹ Ọlọrun fi ọkan wọn le Ẹlẹdaa olootọ lọwọ pẹlu ni rere ṣiṣe.” (1Pétérù 4:17-19)
Njẹ o ri bayi? Bi o tilẹ jẹ wipe gbogbo awa ti a jẹ Kirisitiẹni naa yoo si pada duro siwaju itẹ Kirisiti lati gba ohun ti o tọ si wa fun bi a ti ṣe lo aye wa ninu rẹ, idajọ Ọlọrun ti n lọ lọwọlọwọ laarin wa. O n lọ nipasẹ ibawi ọrọ rẹ. O n lọ nipasẹ ibawi ijiya nipa ti ara, eyi ti o le ni i ṣe pẹlu aisan, iku, aini, idojuti ati bẹẹbẹẹ lọ. O si n waye ki a ba le jẹ ki ijọ Ọlọrun wa ni ailabawọn ni iṣe nigba ti Jesu Kirisiti Oluwa wa ba de – o n waye ki a ma ba da wa lẹbi ati pa wa run pẹlu awọn ti aye yi. (Wo: Málákì 2:7-9; 1Kọ́ríntì 11:28-32; Ìfihàn 2-3)
Niwọn igba ti eyi si wa ri bẹ, niwọn igba ti o jẹ wipe agbole igbagbọ gan ni idajọ Ọlọrun ti kọkọ bẹrẹ, ibo ni awọn ti ko gba iyinrere fẹ sapamọ si? Ko si. Nitorina, o ye ki a ma fi igba gbogbo fi sọkan pe o di dandan ki Ọlọrun pin ẹnikọọkan ni ere iṣẹ ọwọ rẹ. Nigba ti ọrọ si ti ri bayi, ti a ba tilẹ ni lati jiya nitori orukọ Jesu ati ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun, nṣe ni ki a fi idajọ le lọwọ, ki a si ma dẹkun iṣẹ rere ni ṣiṣe.
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Wipe a n gbe igbe aye ti o dun mọ Ọlọrun ninu ko ni ki a ma ṣe inunibini wa, ki a si tun jẹ wa niya pẹlu. Amọ, niwọn igba ti ijiya wa gẹgẹ bi Kirisitiẹni ba ti wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun, ti ko ki i ṣe afọwọfa, nṣe ni ki a tújúká, ki a ma yọ, ki a ma yin Ọlọrun logo, ki a si tun ma ko ẹdun ọkan wa le lọwọ nipasẹ adura gbigba, dipo ti a o fi ma kun tabi sọ ọrọ odi. Idi si ni pe ọjọ naa n bọ ti ẹkun wa yoo di ẹrin, ti ayọ wa yoo di ẹkunrẹrẹ, ti Ọlọrun yoo si san gbogbo awọn ti o n ṣe wa nibi lẹsan iṣẹ ọwọ wọn.
ÌBÉÈRÈ
– Bawo ni ijiya bi Kirisitiẹni ṣe yatọ si irufẹ awọn ijiya miran ti awọn eniyan le jẹ?
Láti ọwọ́ Johnson O. Lawal
Copyright © 2024 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07025105978)
ÀKỌ́RÍ: 1PÉTÉRÙ 3 – YA JÉSÙ SỌ́TỌ̀ BÍ OLÚWA | ÀYỌKÀ: 1PÉTÉRÙ 3:1-22 | ỌJỌ́RÚ 13, ẸRẸ́NÀ 2024
ÀKỌ́SÓRÍ: “Ṣugbọn ẹ bọwọ fun Kirisiti bi Oluwa ni ọkan yin: ki ẹ si mura tan nigba gbogbo lati da olukuluku lohun ti n bere ireti ti o bẹ ninu yin, ṣugbọn pẹlu ọkan tutu ati ibẹru.” (1Peteru 3:15)
Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ
Lẹta Apọsiteli Peteru akọkọ si awọn ọmọ Ọlọrun kaakiri agbaye ni igba aye rẹ jẹ ọkan pataki lara awọn iwe inu bibeli ti o n fi bi a ti ṣe n gbe igbe aye gẹgẹ bi Kirisitiẹni ninu aye ti o kun fun ẹṣẹ ati awọn alaigbagbọ han wa. O si ṣe pataki ki ọmọ Ọlọrun kọọkan ri daju pe oun n ka lẹta yi loorekoore. Idi si ni pe ko fẹrẹ si abala igbe aye onigbagbọ ti ko mẹnuba. Ninu lẹta naa, a sọ nkan ti o ṣẹlẹ si wa nigba ti a gba Jesu gbọ fun wa ati nkan ti igbagbọ wa ninu rẹ yoo pada jasi fun wa. A tun sọrọ nipa bi a tile dagbasoke ninu ẹmi ninu lẹta naa ati irufẹ igbe aye ti o yẹ ki awọn ọmọ Ọlọrun ma a gbe ni ipokipo ti wọn ba ba ara wọn ati irufẹ idojukọ yowu ti wọn le ma a ba pade. Adura mi si ni pe, bi a ti ṣe n kẹkọ ninu iwe yi, ki ẹmi Ọlọrun ṣi oju wa si awọn nkan ti O fẹ ki o jẹ ẹkọ fun wa ninu rẹ, ki O si tun fun wa ni okun lati ṣe amulo awọn nkan wọnyi ni ọna ti o peye, ni orukọ Jesu Kirisiti Oluwa wa. Amin.
ÌGBÀGBỌ́ SÍ ÌGBÀLÀ
Bi a ti ri ninu lẹta yi, bi o tilẹ jẹ wipe Peteru ni o kọ ọ, nipasẹ Sila, ẹni ti o n naa jẹ apọsiteli, ni o ṣe kọ ọ lati fi han wa pe igbe aye igbagbọ ninu Kirisiti ni igbe aye oore-ọfẹ Ọlọrun nitootọ. (1Peteru 5:12). Nitorina, nṣe ni o yẹ ki a duro ṣinṣin ninu igbagbọ wa ninu rẹ. Lotitọ, ọpọ ni yoo fẹ ki o ye wa pe igbe aye ti awọn ẹsin wọn gbe le wọn lọwọ ni igbe aye ti o tọna niwaju Ọlọrun. Amọ, apọsiteli yi fẹ ki a mọ daju pe igbe aye igbagbọ ninu Kirisiti nikan ni igbe aye ti o tọna niwaju Ọlọrun. Ẹni ti ko ba si gba eyi gbọ, ki o si bẹrẹ si ni gbe ile aye rẹ ni ibamu pẹlu rẹ kan fẹ fi aye rẹ ati iwa rere rẹ ṣofo ni.
Ki a ma fa ọrọ gun, Peteru bẹrẹ lẹta yi nipa fifi ara rẹ han gẹgẹ bi ẹni ti o kọ ọ ati nipa jijẹ ki a mọ awọn ti o kọ ọ si. O sọ wipe:
“Peteru, Apositeli Jesu Kirisiti, Si awọn ayanfẹ Ọlọrun, ti wọn n ṣe atipo ni agbaye , ti wọn tu kaakiri si Pọntu, Galatia, Kapadokia, Esia ati Bitinia, awọn ẹni ti a ti yan gẹgẹ bi imọtẹlẹ Ọlọrun Baba, nipa isọdimimọ Ẹmi, si igbọran ati ibuwọn ẹjẹ Jesu Kirisiti: Ki oore-ọfẹ ati alaafia maa bi si fun yin.” (1Pétérù 1:1-2)
Pẹlu agbekalẹ Peteru yi, awọn wo ni a kọ iwe yi si? Awọn ayanfẹ Ọlọrun ni, awọn ayanfẹ rẹ ti n ṣe atipo ni agbaye. Bi awọn ayanfẹ yi si ti wa kaakiri agbaye ni igba yẹn naa ni wọn tun wa kaakiri ni oni. Amọ ibi yowu ti wọn le wa, niwọn igba ti wọn ba ti jẹ ayanfẹ Ọlọrun ninu Kirisiti Jesu, awọn ni a kọ lẹta yi si. Yoo si dara pupọ ki wọn kọbiara si awọn nkan ti a kọ sinu rẹ fun wọn.
Yatọ si eyi, Peteru tun jẹ ki o ye wa pe didi ayanfẹ Ọlọrun ko ki i ṣeeṣi waye. Ọlọrun ti mọ awọn ti yoo jẹ tirẹ ki O to fi idi aye yi lọlẹ. Nitorina, wọn jẹ awọn ti a ya sọtọ, ti a si sọ di mimọ nipasẹ Ẹmi Ọlọrun lati jẹ olugbọnran si aṣẹ Ọlọrun. Ti o ba wa wa lara awọn wọnyi, nṣe ni o yẹ ki o ma ki ara rẹ ku oriire, ki o si ma fi ojoojumọ fi ogo fun Ọlọrun. (Wo: Éfésù 1:4)
Ki wa ni nkan akọkọ ti Peteru fẹ ki o ye awọn ayanfẹ Ọlọrun ninu Kirisiti ti o kọ lẹta yi si? Oun naa ni pe igbagbọ wọn ninu Kirisiti Jesu ki i ṣe lasan – o ni ere. Ki si ni ere igbagbọ yi? Igbala ati ogun ayeraye ni! Iwọ naa wo bi o ti ṣe sọ ọ:
“Iyin yẹ Ọlọrun ati Baba Jesu Kirisiti Oluwa wa! Ẹni ti o tun wa bi gẹgẹ bi aanu nla rẹ sinu ireti aaye nipa ajinde Jesu Kirisiti kuro ninu oku, ati sinu ogun aidibajẹ, ati ailabawọn, ati eyi ti ki i sa, ti a ti fi pamọ ni ọrun de yin, Ẹyin ti a n pamọ nipa agbara Ọlọrun nipa igbagbọ si igbala, ti a mura lati fihan ni igba ikẹyin. Ẹ yọ ninu eyi pupọ, bi o tilẹ jẹ pe nisinsinyi fun igba diẹ, niwọn bi o ti yẹ, a ti fi ọpọlọpọ idanwọ ba yin ninu jẹ: Awọn wọnyii si waye ki idanwo igbagbọ yin ti o ni iye lori ju wura, ti n ṣegbe lọ, bi o tilẹ jẹ pe ina ni a fi n dan an wo, le yọrisi iyin ati ogo ati ọla ni igba ifarahan Jesu Kirisiti. Ẹni ti ẹyin fẹ lairi, ẹni ti ẹyin gbagbọ, bi o tilẹ jẹ pe e ko ri i nisinsinyi, ẹyin si n yọ ayọ ti a ko le fi ẹnu sọ, ti o si kun fun ogo; ẹyin si n gba ilepa igbagbọ yin, ani igbala ọkan yin.” (1Pétérù 1:3-9)
Ki ni nkan akọkọ ti Peteru n jẹ ki o yewa pe o ṣẹlẹ si wa nigba ti a gba Jesu gbọ? Oun naa ni pe a tun wa bi nipasẹ ajinde Jesu sinu ireti aaye ati sinu ogun aidibajẹ, alailabawọn ati eyi ti ki i ṣa, ti a si fi pamọ si ọrun fun wa. Ṣe eyi wa tọpẹ tabi ko tọpẹ? O ma tọpẹ kẹ. O tọpẹ pe Ọlọrun ti sọ wa di ẹda tuntun ati wipe bi a ko tilẹ ri ogun awọn obi wa jẹ laye yi tabi ri nkankan fi silẹ fun awọn ọmọ wa, Ọlọrun ti ṣeto ogun tirẹ silẹ fun wa. Ogun yi si jẹ eyi ti a ko le sọnu, ti ole ko le jigbe ati ti ko le dibajẹ.
Yatọ si iyẹn, ogun ti a n sọrọ nipa rẹ yi ko ni nkankan ṣe pẹlu iṣẹ ọwọ wa rara. Lotitọ, a kọ wa ninu iwe mimọ pe ki a ma pọ si ni rere ṣiṣe ki a ba le to iṣura rere jọ fun ara wa ni ọrun (Mátíù 6:19-21; 1Tímótì 6:17-19). Ṣugbọn boya a to iṣura jọ fun ara wa ni ọrun tabi a ko to ọ jọ, Ọlọrun ti pese ogún ti O fẹ fun wa silẹ. O si pese rẹ silẹ fun wa nitori igbagbọ wa ninu ọmọ rẹ. Nitorina, bi o tilẹ dabi ẹni pe gbigba Jesu gbọ ko ni ere lori laye yi, ọjọ n bọ ti yoo ye gbogbo eniyan dajudaju pe ere ti ko ṣe fẹnusọ ni o wa nidi ki a gba Jesu gbọ ni ibamu pẹlu nkan ti Ọlọrun sọ lori rẹ.
Ki wa ni yoo jẹ ki a nipin ninu ogun ayeraye ti a n sọ yi? Peteru sọ wipe igbala ọkan wa ni. Igbala ọkan wa bawo? Ṣebi a ti gba ọkan wa la nigba ti a gba Jesu gbọ. Igbala wo ni a tun wa n sọrọ nipa? Lotitọ, a ti gba ọkan wa la nipasẹ igbagbọ wa ninu Jesu. Ṣugbọn ipele igbala mẹta ni a fi han wa ninu bibeli. Ipele akọkọ ni igbala ọkan wa kuro lọwọ ijiya ẹṣẹ ati agbara Satani (Kólósè 1:13). Ipele igbala keji ni igbala ti a n fi ojoojumọ ni iriri rẹ kuro lọwọ iṣẹ eṣu, iṣẹ ẹṣẹ ati itanjẹ aye yi. Idi niyi ti Pọọlu ṣe sọrọ nipa awọn ti o n ṣegbe ati awọn ti a n gbala (1Kọ́ríntì 1:18; 2Kọ́ríntì 2:15).
Ṣe o ri, niwọn igba ti eniyan ba si wa laaye, a ko le sọ wipe o ti ṣegbe, bi ko tilẹ ti gba Jesu gbọ ni Oluwa ati Olugbala rẹ. O si n ṣegbe ni. Igba ti o ba ku sinu ipo aigbagbọ rẹ ni a to le sọ wipe o ti ṣegbe. Nibakanna, niwọn igba ti eniyan ba si wa laaye, iriri igbala rẹ ko i ti pari. Idi si ni pe eṣu, ẹṣẹ, aye ati ẹran-ara yoo si ma gbogun ti lati doju igbagbọ rẹ dele. Ṣugbọn, gẹgẹ bi Peteru ti jẹ ki o ye wa ninu awọn ẹṣẹ lẹta rẹ ti o wa loke yẹn, agbara Ọlọrun n pa irufẹ ẹni bẹẹ mọ si igbala nitori igbagbọ rẹ. Nitorina, dipo ki igbagbọ rẹ kuna nitori oniruuru idojukọ ti o n ba a pade, nṣe ni yoo ni okun si i, ti yoo si yọri si ogo ati ọla nigba ti Jesu Oluwa wa ba pada de.
Irufẹ igbala wo wa ni a n sọ nibẹyẹn? Igbala ayeraye ni. Jesu ti ṣiṣẹ igbala yi. Amọ, igba ti a ba to kuro ni aye yi ni a o to ni iriri igbala ayeraye yi kuro lọwọ ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu iṣẹ eṣu, ẹṣẹ, ẹran-ara ati aye. Niwọn igba ti a ba wa wa ninu aye yi, a gbọdọ ma fi igba gbogbo ṣe amulo oore-ọfẹ ati agbara Ọlọrun lati ri pe igbagbọ wa yọri si iriri igbala ayeraye yi (Fílípì 2:13).
Nkan ti a n sọ ni pe, bi o tilẹ jẹ wipe a ko ri Jesu soju ri, igbagbọ wa ninu rẹ ati ifẹ wa fun, eyi ti o n jẹ ki a fi ojoojumọ sin in, lere ti ko ṣe fẹnusọ lori. Peteru tilẹ tẹsiwaju lati jẹ ki o ye wa pe awọn wolii atijọ ti wọn sọ tẹlẹ nipa asiko oore-ọfẹ yi fẹ lọkan wọn lati tọ ọ wo, lati wa láàyè nigba ti yoo ṣeeṣe ki a tun eniyan bi. Bẹẹ si ni, o tun wu awọn angẹli pẹlu lati kopa ninu oore-ọfẹ ti a ni lati jẹ ajogun ohun gbogbo ti Ọlọrun ni ti ki i dibajẹ. (Wo: 1Pétérù 1:10-12)
Nitorina, a ko gbọdọ jẹ ki ẹnikẹni tan wa jẹ tabi gba igbagbọ wa danu kuro lọwọ wa. Dipo bẹẹ, Peteru sọ wipe nṣe ni o yẹ ki a ṣe ọkan wa giri lati gbe igbe aye iwa mimọ ati ikora-ẹni-nijanu ati lati fojusọna fun iriri igbala ayeraye wa ti yoo waye nigba ti Jesu Kirisiti Oluwa wa ba farahan. Ki a si ṣe eyi nipa fifiyesi awọn nkan wọnyi:
– Mímọ́ ni ẹni tí ó pè wá: Peteru, ninu lẹta yi sọ wipe, “Ṣugbọn gẹgẹ bi ẹni ti o pe yin ti jẹ mimọ; bẹẹ ni ki ẹyin naa jẹ mimọ. Nitori a ti kọ ọ pe, “Ẹ jẹ mimọ: nitori ti Emi jẹ mimọ!”” (1Pétérù 1:15-16) Ki ni itumọ eyi? Oun naa ni pe mimọ ni Ọlọrun Baba wa, ti O pe wa, ti O tun wa bi, ti O si ya wa sọtọ. Nitorina, ti a ba jẹ ọmọ rẹ nitootọ, igbe aye iwa mimọ ni a gbọdọ fi ara wa jin fun ninu aye eeri ati idibajẹ yi.
– Ọlọ́run yóò ṣe ìdájọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan: Idi keji ti a fi gbọdọ fi ara wa jin fun iwa mimọ ni pe Ọlọrun yoo ṣe idajọ ẹnikọọkan ti o gbe ile aye yi lọjọ kan. Ko si wa si ojuṣaaju pẹlu rẹ. Nitorina, ki a ma ro wipe a le pe ara wa ni ọmọ Ọlọrun, ki a si tun ma ṣe ohun ti o wu wa. Ẹni ti ko ba gbe igbe aye rẹ bi ọmọ Ọlọrun ko gbọdọ reti pe ki Ọlọrun fun ni ere ti o tọ si awọn ọmọ rẹ. (Wo: 1Pétérù 1:17)
– A ti ràwá padà àti tún wa bí: Nkan kẹta ti a gbọdọ fiyesi ni gbigbe igba aye iwa mimọ ni pe a ti ra wa pada kuro ninu igbe aye asan ti a jogun lati ọwọ awọn baba-nla wa. A si tun ti tun wa bi. Ki wa ni a fi ra wa pada lati ma gbe igbe aye asan mọ? Ṣe owo ni? Ṣe wura tabi fadaka ni? Rara! Ẹjẹ Jesu Kirisiti ti O ku fun wa ni a fi san gbese ẹṣẹ ati igbesi aye asan wa. Ki si ni a fi tun wa bi? Ṣe nipasẹ agbara ibi ti ẹran-ara ti o ma n dibajẹ tabi ku ni bi? Rara o! Nipasẹ ọrọ Ọlọrun, ọrọ iyinrere rẹ, ti ko ki i dibajẹ, ti a si ti fi waasu si wa, ni a fi tun wa bi. Nitorina, ti a ba n gbe igbe aye asan, igbe aye ẹṣẹ, igbe aye ikorira, nṣe ni a n fi han pe a ko i ti tun wa bi rara tabi wipe a ti gbagbe pe a ti di ẹni ọtọ. (Wo: 1Pétérù 1:18-25)
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Lakotan, koko nkan ti Peteru n fi idi rẹ mulẹ fun wa ni ori kini lẹta rẹ ni pe igbagbọ ninu Jesu Kirisiti lere, o n ṣiṣẹ si igbala ati ogun ayeraye. Nitorina, a ko gbọdọ fọwọ yẹnpẹrẹ mu igbagbọ naa, bi a tilẹ n dojukọ oniruuru igbogun eṣu, ẹṣẹ, ẹran-ara ati aye yi lojoojumọ. Dipo eyi, nṣe ni ki a duro ṣinṣin ninu rẹ ni ireti pe Jesu Oluwa wa yoo de lọjọ kan lati fun wa ni ẹkunrẹrẹ iriri igbala aye ati ọkan wa.
ÌBÉÈRÈ
– Kini o lero pe o n jẹ ki awọn angẹli naa fẹ tọ oore-ọfẹ ti a ni ninu Jesu wo?
– Kini o ṣe pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi?
Láti ọ́wọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2024 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07025105978)
Ninu ẹkọ ti a kọ kọja lọ ninu lẹta Peteru kinni si awọn eniyan Ọlọrun, a ri pe ko to ki a kan sọ pe a ti gba Jesu gbọ ati pe a ti di ẹni igbala; o tun ṣe pataki ki a lepa lati dagbasoke ninu ẹmi. Aijẹbẹ, a le padanu iriri igbala ayeraye ti a titori rẹ dirọ mọ Jesu. Ti a ba si padanu eyi, a jẹ wipe a ko fi igba kankan di ọmọ Ọlọrun niyẹn – eke ni wa. Bawo ni a wa ṣe le dagbasoke ninu ẹmi? Ọna kan pataki lara ọna ti a fi le dagbasoke ninu ẹmi ni pipongbẹ fun ọrọ Ọlọrun ati fifi ara wa jin fun un. Idagbasoke ninu ẹmi wa kọja ọrọ ẹnu – o gbọdọ farahan ninu bi a ti ṣe n sin Ọlọrun ati ninu irufẹ igbe aye ti a n gbe. Nitorina, Peteru tẹsiwaju lati mẹnuba awọn ọna ti a le fi fihan pe a n dagbasoke ninu ẹmi. A si wo ẹyọkan lara rẹ ninu ẹkọ ti a kọ kọja lọ, eyi ti o ni i ṣe pẹlu ki a bọwọ fun awọn ti o ni aṣẹ lori wa. A wa fẹ tẹsiwaju ninu ẹkọ yi, iyẹn ninu ori ikẹta lẹta yi, lati tun wo awọn nkan miran ti Peteru sọ lori gbigbe igbe aye ẹni ti a ti tun bi, ti o si tun n dagbasoke ninu ẹmi.
YA JÉSÙ SỌ́TỌ̀ BÍ OLÚWA
Ki wa ni awọn nkan ti Peteru ba wa sọ ni ori ikẹta lẹta rẹ yi lori bi a ti ṣe fi han pe a ti mọ Jesu nitootọ ati wipe a n dagbasoke ninu ibaṣepọ wa pẹlu rẹ? Akọkọ, o ba wa sọrọ lori bi o ti yẹ ki a ma ṣe gẹgẹ bi lọ́kọ-láya. Eyi tunmọ si pe iyatọ kedere gbọdọ wa laarin iṣeṣi iyawo ti o jẹ Kirisitiẹni ati eyi ti ko ki i ṣe Kirisitiẹni. Bẹẹ si ni pẹlu, iyatọ gedegbe gbọdọ wa laarin ọkọ ti o jẹ Kirisitiẹni ati eyi ti ko ki i ṣe Kirisitiẹni. Aijẹbẹ, ki wa ni ẹkọ ti awọn ti ko ki i ṣe Kirisitiẹni ti ile wọn ko lojutu fẹ kọ lara awa ti a pe ara wa ni ọmọ Ọlọrun? Iwọ naa wo nkan ti Peteru sọ lori ọrọ yi, lakọkọ, si awọn ti o jẹ aya:
“Bẹẹ gẹgẹ, ẹyin aya, ẹ maa tẹriba fun awọn ọkọ yin; pe, bi ẹnikẹni ba tilẹ n ṣe aigbọran si ọrọ naa, ki a le jere wọn ni aisọrọ nipa iwa awọn aya wọn; Nigba ti wọn ba n ri iwa rere ati ibọwọfun yin: Ki ọṣọ yin ma ṣe jẹ ti ode, ti irun didi, ati ti wura lilo; tabi ti aṣọ wiwọ; Ṣugbọn ki o jẹ ti ẹda naa ti o farasin ni ọkan yin; pẹlu ọṣọ aidibajẹ ti ẹmi irẹlẹ ati ẹmi tutu, eyi ti o ṣe iyebiye ju niwaju Ọlọrun. Nitori bayii ni awọn obinrin mimọ igbaani pẹlu, ti wọn gbẹkẹle Ọlọrun, fi ṣe ara wọn ni ọṣọ, wọn a maa tẹriba fun awọn ọkọ wọn. Gẹgẹ bi Sera ti gbọ ti Aburahamu, ti o si n pe e ni oluwa: ọmọbinrin rẹ si ni ẹyin n ṣe, bi ẹyin ba n ṣe rere, ti ohunkohun ko si dẹruba yin.” (1Pétérù 3:1-6)
Kini nkan akọkọ ti yoo fi han pe Kirisitiẹni lotitọ ni obinrin ti o wa ni ile ọkọ rẹ? Itẹriba! Bi Peteru ti ṣe jẹ ki o ye wa, yala ọkọ rẹ jẹ Kirisitiẹni tabi ko ki i ṣe Kirisitiẹni, aya gbọdọ tẹriba fun ọkọ rẹ, ki o si tun bọwọ fun un. O si fi Sera, aya Aburahamu, ṣe apejejuwe irufẹ itẹriba ti awọn aya ti o jẹ onigbagbọ ninu Kirisiti gbọdọ fun awọn ọkọ wọn. Sera a ma pe ọkọ rẹ ni oluwa. Eyi ko tunmọ si pe ẹru Aburahamu ni o jẹ. Ṣugbọn o tunmọ si pe o ka si ẹni ti o yẹ ki oun bọwọ fun gidigidi. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 18:12)
Nibakanna, gbogbo awọn aya ti o jẹ Kirisitiẹni ni o yẹ ki wọn fi han pe Jesu ti gba akoso aye awọn nitootọ nipa bibu ọla ti o peye fun awọn ọkọ wọn. Wọn ko gbọdọ ma ba wọn ja tabi ma tabuku wọn. Yatọ si bibu ọla fun awọn ọkọ wọn, wọn tun gbọdọ fi ara wọn jin fun iṣẹ rere ṣiṣe ninu ile wọn. Eyi ni Ọlọrun ka si ọṣọ ododo, ki i ṣe ki a kan di irun tabi ki a wọ aṣọ olowo iyebiye.
Ki wọn ni anfaani tabi ere ti o wa ninu ki wọn ma ṣe bi eyi? Akọkọ, bi Peteru ti jẹ ki o ye wa, nipa ṣiṣe eyi, Ọlọrun le ri awọn aya wọnyi lo lati yi awọn ọkọ wọn ti ko gbagbọ tabi ti igbe aye Kirisitiẹni tootọ ko ye pada, bi ẹnikẹni to tilẹ waasu si wọn. Lotitọ, o ṣe pataki ki a ma waasu iyinrere Jesu si awọn eniyan. Amọ iwaasu nikan ko to lati yi awọn kan pada. Ti wọn ko ba ri iṣẹ rere ti gbigba Jesu gbọ n ṣe ninu aye awọn ti o sunmọ wọn pẹkipẹki, wọn le ma gbagbọ.
Wayi o, pe alaigbagbọ wa ri iwa rere wa ko tunmọ si pe dandanla yoo gba Jesu gbọ. O le ma gba a gbọ. Idi si niyi ti o fi san ki ẹnikẹni ti o ba fẹ ni ọkọ tabi aya gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun ri daju pe ọmọ Ọlọrun miran ni oun fẹ. Ki o ma ṣe lero rara pe ti oun ba tilẹ fẹ alaigbagbọ, oun o le yi iwa rẹ pada nipasẹ iwa rere oun. Ọlọrun ni o ma n yi awọn eniyan pada. Ẹni ti ko ba si yi pada, irinwó iwaasu ati ẹgbẹrun iṣẹ rere le ma to lati yi aye rẹ pada.
Anfaani keji ti o wa ninu ki awọn aya ma teriba fun ọkọ, ki wọn ma bọwọ fun wọn, ki wọn si tun ma fi ara wọn jin fun iṣẹ rere ni pe yoo fun wọn ni igboya lati gbe ile aye wọn. Ọpọ obinrin ni o n gbe ninu ibẹru tabi aibalẹọkan ninu ile wọn. Ara awọn nkan ti o si ma n fa ni pe iwa ọwọ wọn ko mọ. Bi Ọlọrun ti ṣe sọ fun Keni ki o tọ pa aburo rẹ Abẹli, ti a ba ṣe rere, ara yoo ya wa. Ṣugbọn ti a ko ba fi ara wa jin fun rere, ibẹrubojo ko ni jinna si wa. Nitorina, bi ọkọ rẹ ko tilẹ mọ Ọlọrun, ri daju, gẹgẹ bi aya, pe iwa rẹ ninu ilẹ pẹlu rẹ wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun. Eyi yoo fun ọ ni igboya lati gbe ile aye rẹ pẹlu ifọkanbalẹ.
Ko ki wa ṣe kiki awọn aya ti o jẹ Kirisitiẹni nikan ni ọrọ yi kan; o kan awọn ọkọ ti o jẹ Kirisitiẹni naa. Lọna wo? Wo nkan ti Peteru sọ lori eyi:
“Bẹẹ gẹgẹ ẹyin ọkọ, ẹ maa fi oye ba awọn aya yin gbe, ki ẹ si maa bu ọla fun wọn gẹgẹ bi ohun elo ti ko lagbara, ati pẹlu bii ajumọ-jogun oore-ọfẹ iye; ki adura yin ki o ma baa ni idena.” (1Pétérù 3:7)
Bawo ni ki awọn ọkọ ti o jẹ Kirisitiẹni ma ṣe si awọn aya wọn? Akọkọ, Peteru ni ki wọn ma fi oye ba wọn lo. Iyẹn tunmọ si pe wọn gbọdọ ni suuru pẹlu awọn aya wọn. Aijẹbẹ ọpọ igba ni ija yoo ma waye laarin wọn. Ekeji, Peteru ni ki wọn ri awọn aya wọn gẹgẹ bi ohun elo ti ko lagbara ati gẹgẹ bi ọkanna pẹlu wọn ninu Kirisiti. Niwọn igba ti wọn ba n ri wọn lọna yi, wọn yoo ma bu ọla ti o tọ fun wọn. Eyi jẹ ki o ye wa pe bi o ti ṣe ṣe pataki ki awọn aya bọwọ fun awọn ọkọ naa ni o ṣe ṣe pataki ki awọn ọkọ naa ba bu ọla fun awọn aya wọn. Ọlọrun ko fi aye gba ọkọ Kirisitiẹni lati ma sọrọ kobakungbe si aya rẹ tabi lati ma lu wọn tabi lati ma pọn wọn loju.
Awọn ọkọ ti ko ba wa tẹle ọrọ yi le ba idena adura wọn pade, gẹgẹ bi Peteru ti ṣe sọ. Ọpọ idile onigbagbọ ni ko si ni ilọsiwaju ti o peye nitori eyi. Wọn le ma gbadura, ki wọn si tun ma gba awẹ. Amọ, niwọn igba ti wọn ko ba ti ma tẹle ọrọ Ọlọrun ni fifi ifẹ, ọwọ ati ọla ba ara wọn lo pọ, ko si bi awọn adura wọn kọọkan ko ṣe ni ma ba idena pade.
Awọn ọkunrin nikan kọ si ni eyi bawi. O ba awọn obinrin wi pẹlu. Nitorina, ni ile wa, gẹgẹ bi ọkunrin onigbabọ ati obinrin onigbagbọ, o ṣe pataki ki a fi han pe Jesu ni Oluwa wa nitootọ. Eyi yoo jẹ ki awọn alaigbagbọ ti o wa ni agbegbe wa ri wa bi awọkọṣe rere ati bi ẹni ti wọn le fi ọrọ aye wọn tabi ile wọn lọ.
Amọ ṣa o, ko ki i ṣe ninu ile wa nikan ni o ti yẹ ki a fihan pe Jesu ni Oluwa wa nitootọ, a tun gbọdọ fi han ninu ibaṣepọ wa pẹlu awọn ara wa ninu Kirisiti, ninu ibaṣepọ wa pẹlu awọn ti o wa ni awujọ wa ati ninu isọrọsi wa. Wo diẹ lara nkan ti Peteru sọ lori eyi:
“Lakootan, ki gbogbo yin jẹ oninu kan, ẹ maa ba ara yin kẹdun, ẹ ni ifẹ ara, ẹ maa ṣe iyọnu, ẹ ni ẹmi irẹlẹ. Ẹ ma ṣe fi buburu san buburu tabi fi eebu san eebu: ṣugbọn kaka bẹẹ, ẹ maa sure; nitori eyi ni a pe yin si, ki ẹyin le jogun ibukun. Nitori, “Ẹni ti yoo ba fẹ iye, ti yoo si ri ọjọ rere, ki o pa ahọ rẹ mọ kuro ninu ibi, ati ete rẹ mọ kuro ninu sisọ ọrọ ẹtan: Ki o ya kuro ninu ibi, ki o si maa ṣe rere: ki o maa wa alaafia, ki o si maa lepa rẹ. Nitori oju Oluwa n bẹ lara awọn olododo, eti rẹ si ṣi si ẹbẹ wọn: ṣugbọn oju Oluwa dojukọ awọn ti n ṣe buburu.” Ta ni yoo si ṣe yin ni ibi, bi ẹyin ba jẹ onitara si ohun rere? Ṣugbọn bi ẹyin ba jiya nitori ododo, alaafia ni: ẹ ma si ṣe kọminu; Ṣugbọn ẹ bọwọ fun Kirisiti bi Oluwa ni ọkan yin: ki ẹ si mura tan nigba gbogbo lati da olukuluku lohun ti n bere ireti ti o n bẹ ninu yin; ṣugbọn pẹlu ọkan tutu ati ibẹru. Ki ẹ maa ni ẹri-ọkan rere bi wọn ti n sọrọ yin ni ibi, ki oju le ti awọn ti n kẹgan iwa rere yin ninu Kirisiti” (Pétérù 3:8-16)
Njẹ o ri bayẹn? Ninu awọn ijọ wa, a gbọdọ wa ni iṣọkan, ki a si ma fi ifẹ mojuto ara wa. Aijẹbẹ, ko si bi awọn ara ita ṣe fẹ ri wa gẹgẹ bi ọmọlẹyin Kirisiti nitootọ. Ranti pe Jesu Oluwa wa sọ eyi fun wa:
“Ofin titun kan ni mo fi fun yin, ki ẹyin ki o fẹ ọmọnikeji yin; gẹgẹ bi emi ti fẹran yin, ki ẹyin ki o si le fẹran ọmọnikeji yin. Nipa eyi ni gbogbo eniyan yoo fi mọ pe, ọmọ-ẹyin mi ni ẹyin n ṣe, nigba ti ẹyin ba ni ifẹ si ọmọnikeji yin” (Jòhánù 13:34-35)
Nitorina, a gbọdọ ma fi ifẹ otitọ ba awọn ara wa ninu oluwa lo pọ. A ko si gbọdọ fi aye gba igbẹṣan buburu pẹlu buburu. Idi ni wipe o ṣeeṣe ki a ṣe ara wa ninu ijọ tabi ki ẹlomiran ti ko ki i ṣe ọmọ Ọlọrun ṣe wa. Ti a ba wa mọ Jesu nitootọ, ti a si gba ni Oluwa ati Olugbala wa, a ko ni ronu lati fi buburu san buburu fun ẹnikẹni. A ko tilẹ ni fi ẹnu wa silẹ fun Satani lati lo lati ma sọ ọrọ buburu tabi ọrọ alufansa si ẹnikẹni. Bi Peteru si ṣe sọ, irufẹ ọrọ ti o n jade lẹnu wa ni ipa ti o ga lati ko lori irufẹ iriri ti a o ni ni aye yi. Ti ọrọ buruku ba kun ẹnu wa, ọrọ bi-epe-bi-epe, ko si bi iyọnu, ija ati ibanujẹ ko ṣe ni ma a tẹle wa kaakiri, bi o tilẹ jẹ wipe ọmọ Ọlọrun ni a pe ara wa.
Nitorina, gẹgẹ bi Peteru ti ṣe sọ siwaju ninu abala lẹta rẹ ti a n wo yi, a ni lati fihan pe a ti ya Jesu sọtọ ninu aye wa gẹgẹ bi Oluwa wa. Lọna wa? Lakọkọ, nipaṣẹ iwa wa. Lẹkeji, nipasẹ ọrọ ẹnu wa. O tilẹ jẹ ki o ye wa pe ti ẹnikẹni ba bere lọwọ wa lori ireti ti a ni ninu Jesu, nṣe ni ki a fi pẹlẹpẹlẹ ati ọkan tutu da wọn lohun. Niwọn igba ti o ba si jẹ wipe igbe aye iwa rere yi ni a n gbe, a ko nilo lati bẹru ẹnikẹni.
Wayi ọ, bi Peteru ṣe wa tun jẹ ki o ye wa, wipe a n gbe igbe aye iwa rere, igbe aye ẹni ti o ti ya Jesu sọtọ gẹgẹ bi Oluwa rẹ, ko jasi pe ki awọn eniyan ma kẹgan wa. Wọn le kegan wa. Wọn tilẹ tun le gbogun ti wa lati jẹ wa niya nitori iwa mimọ wa. Amọ, a ko gbọdọ jẹ ki eyi bi wa ninu tabi fa irẹwẹsi si ọkan wa. Ki si ni idi? Idi ni yi, gẹgẹ bi ọrọ Peteru:
“Nitori o san, bi o ba jẹ ifẹ Ọlọrun, ki ẹ jiya fun ṣiṣe rere ju fin ṣiṣe buburu lọ. Nitori ti Kirisiti pẹlu jiya lẹẹkan nitori ẹṣẹ wa, gẹgẹ bi oloootọ fun awọn alaiṣootọ, ki o le mu wa de ọdọ Ọlọrun, ẹni ti a pa ninu ara, ṣugbọn ti a sọ di aaye ninu ẹmi: Ninu eyi ti o lọ pẹlu ti o si waasu fun awọn ẹmi ninu tubu: Awọn ti o ṣe alaigbọran nigba kan, nigba ti suuru Ọlọrun duro pẹ ni ṣaa kan ni ọjọ Noa, nigba ti wọn fi kan ọkọ ninu eyi ti a gba awọn diẹ la nipa omi, eyi ni ẹni mẹjọ. Apẹẹrẹ eyi ti n gba yin la nisinsinyii pẹlu, ani itẹbọmi, ki i ṣe wiwẹ eeri ti ara nu, bi ko ṣe idahun ẹri ọkan rere si Ọlọrun, nipa ajinde Jesu Kirisiti. Ẹni ti o lọ si ọrun, ti o si n bẹ lọwọ ọtun Ọlọrun: pẹlu awọn angẹli, awọn alaṣẹ, ati alagbara si tẹriba labẹ rẹ.” (1Pétérù 3:17-22)
Njẹ o ri bayi? Ti o ba jẹ ifẹ Ọlọrun, o san fun wa lati jiya fun ṣiṣe rere dipo fun wiwu iwa buburu. Eyi n fi ye wa pe ko ki i ṣe gbogbo igba ni o ma n jẹ ifẹ Ọlọrun fun awọn eniyan rẹ lati jẹ iya aitọ. Ti ijiya aitọ wa ko ba ni fi ogo fun Ọlọrun tabi la ọna igbala fun awọn miran, ko ni lọwọ si. A si ri apẹrẹ eyi ninu Jesu. Ijiya ati iku rẹ jẹ eyi ti ko tọ rara. Amọ, nitoripe yoo yọri si igbala araye, Ọlọrun fi ọwọ si. Nitorina, a ko gbọdọ kan ti ara wa sẹnu iya tabi iku nitoripe awa naa fẹ dabi Jesu. Ti o ba ṣeeṣe fun wa lati yẹra fun ijiya aitọ lalai ṣe wipe a ṣẹ orukọ Jesu, njẹ nṣe ni ki a yẹra fun. Ṣugbọn ti o ba jẹ wipe a ko ri ibi yẹ ẹ ṣi, nṣe ni ki a tẹwọgba bi Jesu ti ṣe ṣe, fun ogo ati ọla Ọlọrun.
Bi Peteru ti ṣe jẹ ki o ye wa, bi o tilẹ jẹ wipe Jesu ku iku ẹṣẹ nipa ti ara fun gbogbo araye, Ọlọrun sọ ọ di aye nipa ti ẹmi. Idi si ni pe ko mọ ẹṣẹ ri. Nitorina a ko fi silẹ si ọrun apadi gẹgẹ bi ẹlẹṣẹ. Dipo bẹẹ, lakọkọ, a da a lare. O si waasu nipa ara rẹ fun awọn ẹmi ti o wa ninu tubu.
Awọn emi wo wa ni eyi? Akọkọ naa, a pe wọn ni ẹmi, eyi ti o tunmọ si pe wọn ko ki i ṣe eniyan. Ekeji, a sọ wipe wọn ṣe aigbọran nigba aye Noa, ki ikun omi to waye. Eyi n jẹ ki o ye wa pe awọn angẹli ti o fi aye wọn silẹ lati ba awọn ọmọ eniyan ni ajọsepọ ni a n sọrọ nipa. Awọn ni Ọlọrun ti mọ inu tubu bi a ti ṣe tun mẹnuba ni awọn abala bibeli miran. Ki wa ni koko iwasu Jesu si awọn ẹmi yi? Oun naa ni lati jẹ ki wọn mọ pe oun ni Ọlọrun ti fi ṣe Oluwa ati alaṣẹ lori ohun gbogbo. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 6:1-4; Fílípì 2:5-11; 2Pétérù 2:4; Júùdù 6)
Lẹyin eyi, a ji Jesu dide nipa ti ara, a si tun gbe lọ si ọwọ ọtun Ọlọrun, ti gbogbo awọn angẹli ati gbogbo awọn alaṣẹ ati alagbara laye ati lọrun ati ni isalẹ ilẹ si wa ni itẹriba labẹ rẹ. Eyi si ni o jẹ ki awọn ti o gbagbọ ninu rẹ le di ẹni igbala nipasẹ rẹ. Peteru tilẹ jẹ ki o ye wa pe igbala Noa ati awọn ti o wa pẹlu rẹ ninu ọkọ oju omi rẹ lọjọkinni-ana jẹ apẹrẹ bi awa naa ṣe di ẹni igbala nipasẹ itẹbọmi wa ninu Kirisiti. Amọ eyi kọja ki a kan ti eniyan bọ omi lasan lati wẹ eeri ara rẹ nu; eyi ni i ṣe pẹlu ijẹri otitọ ninu ọkan wa lati jẹ ti Ọlọrun nipasẹ ajinde Jesu Krisiti.
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Sisọ wipe a jẹ ọmọ Ọlọrun pẹlu ẹnu wa ko to; o tun ṣe pataki ki a ya Jesu sọtọ ninu ọkan wa gẹgẹ bi Oluwa ati alaṣẹ lori aye wa nitootọ. Ti a ba si ti ṣe eyi, o di dandan ki o farahan ninu igbesi aye wa ninu ile wa, laarin awọn ọmọ Ọlọrun miran ati laarin awọn ti aye yi.
ÌBÉÈRÈ
– Ki ni o ri kọ ninu ẹkọ yi?
Láti ọwọ́ Johnson O. Lawal
Copyright © 2024 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07025105978)
ÀKỌ́RÍ: 1PÉTÉRÙ 1 – ÌGBÀGBỌ́ SÍ ÌGBÀLÀ | ÀYỌKÀ: 1PÉTÉRÙ 1:1-25 | ỌJỌ́RÚ 31, SẸRẸ 2024
ÀKỌ́SÓRÍ: “Ẹyin si n gba ere igbagbọ yin, ani igbala ọkan yin.” (1Pétérù 1:9)
Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ
Lẹta Apọsiteli Peteru akọkọ si awọn ọmọ Ọlọrun kaakiri agbaye ni igba aye rẹ jẹ ọkan pataki lara awọn iwe inu bibeli ti o n fi bi a ti ṣe n gbe igbe aye gẹgẹ bi Kirisitiẹni ninu aye ti o kun fun ẹṣẹ ati awọn alaigbagbọ han wa. O si ṣe pataki ki ọmọ Ọlọrun kọọkan ri daju pe oun n ka lẹta yi loorekoore. Idi si ni pe ko fẹrẹ si abala igbe aye onigbagbọ ti ko mẹnuba. Ninu lẹta naa, a sọ nkan ti o ṣẹlẹ si wa nigba ti a gba Jesu gbọ fun wa ati nkan ti igbagbọ wa ninu rẹ yoo pada jasi fun wa. A tun sọrọ nipa bi a tile dagbasoke ninu ẹmi ninu lẹta naa ati irufẹ igbe aye ti o yẹ ki awọn ọmọ Ọlọrun ma a gbe ni ipokipo ti wọn ba ba ara wọn ati irufẹ idojukọ yowu ti wọn le ma a ba pade. Adura mi si ni pe, bi a ti ṣe n kẹkọ ninu iwe yi, ki ẹmi Ọlọrun ṣi oju wa si awọn nkan ti O fẹ ki o jẹ ẹkọ fun wa ninu rẹ, ki O si tun fun wa ni okun lati ṣe amulo awọn nkan wọnyi ni ọna ti o peye, ni orukọ Jesu Kirisiti Oluwa wa. Amin.
ÌGBÀGBỌ́ SÍ ÌGBÀLÀ
Bi a ti ri ninu lẹta yi, bi o tilẹ jẹ wipe Peteru ni o kọ ọ, nipasẹ Sila, ẹni ti o n naa jẹ apọsiteli, ni o ṣe kọ ọ lati fi han wa pe igbe aye igbagbọ ninu Kirisiti ni igbe aye oore-ọfẹ Ọlọrun nitootọ. (1Peteru 5:12). Nitorina, nṣe ni o yẹ ki a duro ṣinṣin ninu igbagbọ wa ninu rẹ. Lotitọ, ọpọ ni yoo fẹ ki o ye wa pe igbe aye ti awọn ẹsin wọn gbe le wọn lọwọ ni igbe aye ti o tọna niwaju Ọlọrun. Amọ, apọsiteli yi fẹ ki a mọ daju pe igbe aye igbagbọ ninu Kirisiti nikan ni igbe aye ti o tọna niwaju Ọlọrun. Ẹni ti ko ba si gba eyi gbọ, ki o si bẹrẹ si ni gbe ile aye rẹ ni ibamu pẹlu rẹ kan fẹ fi aye rẹ ati iwa rere rẹ ṣofo ni.
Ki a ma fa ọrọ gun, Peteru bẹrẹ lẹta yi nipa fifi ara rẹ han gẹgẹ bi ẹni ti o kọ ọ ati nipa jijẹ ki a mọ awọn ti o kọ ọ si. O sọ wipe:
“Peteru, Apositeli Jesu Kirisiti, Si awọn ayanfẹ Ọlọrun, ti wọn n ṣe atipo ni agbaye , ti wọn tu kaakiri si Pọntu, Galatia, Kapadokia, Esia ati Bitinia, awọn ẹni ti a ti yan gẹgẹ bi imọtẹlẹ Ọlọrun Baba, nipa isọdimimọ Ẹmi, si igbọran ati ibuwọn ẹjẹ Jesu Kirisiti: Ki oore-ọfẹ ati alaafia maa bi si fun yin.” (1Pétérù 1:1-2)
Pẹlu agbekalẹ Peteru yi, awọn wo ni a kọ iwe yi si? Awọn ayanfẹ Ọlọrun ni, awọn ayanfẹ rẹ ti n ṣe atipo ni agbaye. Bi awọn ayanfẹ yi si ti wa kaakiri agbaye ni igba yẹn naa ni wọn tun wa kaakiri ni oni. Amọ ibi yowu ti wọn le wa, niwọn igba ti wọn ba ti jẹ ayanfẹ Ọlọrun ninu Kirisiti Jesu, awọn ni a kọ lẹta yi si. Yoo si dara pupọ ki wọn kọbiara si awọn nkan ti a kọ sinu rẹ fun wọn.
Yatọ si eyi, Peteru tun jẹ ki o ye wa pe didi ayanfẹ Ọlọrun ko ki i ṣeeṣi waye. Ọlọrun ti mọ awọn ti yoo jẹ tirẹ ki O to fi idi aye yi lọlẹ. Nitorina, wọn jẹ awọn ti a ya sọtọ, ti a si sọ di mimọ nipasẹ Ẹmi Ọlọrun lati jẹ olugbọnran si aṣẹ Ọlọrun. Ti o ba wa wa lara awọn wọnyi, nṣe ni o yẹ ki o ma ki ara rẹ ku oriire, ki o si ma fi ojoojumọ fi ogo fun Ọlọrun. (Wo: Éfésù 1:4)
Ki wa ni nkan akọkọ ti Peteru fẹ ki o ye awọn ayanfẹ Ọlọrun ninu Kirisiti ti o kọ lẹta yi si? Oun naa ni pe igbagbọ wọn ninu Kirisiti Jesu ki i ṣe lasan – o ni ere. Ki si ni ere igbagbọ yi? Igbala ati ogun ayeraye ni! Iwọ naa wo bi o ti ṣe sọ ọ:
“Iyin yẹ Ọlọrun ati Baba Jesu Kirisiti Oluwa wa! Ẹni ti o tun wa bi gẹgẹ bi aanu nla rẹ sinu ireti aaye nipa ajinde Jesu Kirisiti kuro ninu oku, ati sinu ogun aidibajẹ, ati ailabawọn, ati eyi ti ki i sa, ti a ti fi pamọ ni ọrun de yin, Ẹyin ti a n pamọ nipa agbara Ọlọrun nipa igbagbọ si igbala, ti a mura lati fihan ni igba ikẹyin. Ẹ yọ ninu eyi pupọ, bi o tilẹ jẹ pe nisinsinyi fun igba diẹ, niwọn bi o ti yẹ, a ti fi ọpọlọpọ idanwọ ba yin ninu jẹ: Awọn wọnyii si waye ki idanwo igbagbọ yin ti o ni iye lori ju wura, ti n ṣegbe lọ, bi o tilẹ jẹ pe ina ni a fi n dan an wo, le yọrisi iyin ati ogo ati ọla ni igba ifarahan Jesu Kirisiti. Ẹni ti ẹyin fẹ lairi, ẹni ti ẹyin gbagbọ, bi o tilẹ jẹ pe e ko ri i nisinsinyi, ẹyin si n yọ ayọ ti a ko le fi ẹnu sọ, ti o si kun fun ogo; ẹyin si n gba ilepa igbagbọ yin, ani igbala ọkan yin.” (1Pétérù 1:3-9)
Ki ni nkan akọkọ ti Peteru n jẹ ki o yewa pe o ṣẹlẹ si wa nigba ti a gba Jesu gbọ? Oun naa ni pe a tun wa bi nipasẹ ajinde Jesu sinu ireti aaye ati sinu ogun aidibajẹ, alailabawọn ati eyi ti ki i ṣa, ti a si fi pamọ si ọrun fun wa. Ṣe eyi wa tọpẹ tabi ko tọpẹ? O ma tọpẹ kẹ. O tọpẹ pe Ọlọrun ti sọ wa di ẹda tuntun ati wipe bi a ko tilẹ ri ogun awọn obi wa jẹ laye yi tabi ri nkankan fi silẹ fun awọn ọmọ wa, Ọlọrun ti ṣeto ogun tirẹ silẹ fun wa. Ogun yi si jẹ eyi ti a ko le sọnu, ti ole ko le jigbe ati ti ko le dibajẹ.
Yatọ si iyẹn, ogun ti a n sọrọ nipa rẹ yi ko ni nkankan ṣe pẹlu iṣẹ ọwọ wa rara. Lotitọ, a kọ wa ninu iwe mimọ pe ki a ma pọ si ni rere ṣiṣe ki a ba le to iṣura rere jọ fun ara wa ni ọrun (Mátíù 6:19-21; 1Tímótì 6:17-19). Ṣugbọn boya a to iṣura jọ fun ara wa ni ọrun tabi a ko to ọ jọ, Ọlọrun ti pese ogún ti O fẹ fun wa silẹ. O si pese rẹ silẹ fun wa nitori igbagbọ wa ninu ọmọ rẹ. Nitorina, bi o tilẹ dabi ẹni pe gbigba Jesu gbọ ko ni ere lori laye yi, ọjọ n bọ ti yoo ye gbogbo eniyan dajudaju pe ere ti ko ṣe fẹnusọ ni o wa nidi ki a gba Jesu gbọ ni ibamu pẹlu nkan ti Ọlọrun sọ lori rẹ.
Ki wa ni yoo jẹ ki a nipin ninu ogun ayeraye ti a n sọ yi? Peteru sọ wipe igbala ọkan wa ni. Igbala ọkan wa bawo? Ṣebi a ti gba ọkan wa la nigba ti a gba Jesu gbọ. Igbala wo ni a tun wa n sọrọ nipa? Lotitọ, a ti gba ọkan wa la nipasẹ igbagbọ wa ninu Jesu. Ṣugbọn ipele igbala mẹta ni a fi han wa ninu bibeli. Ipele akọkọ ni igbala ọkan wa kuro lọwọ ijiya ẹṣẹ ati agbara Satani (Kólósè 1:13). Ipele igbala keji ni igbala ti a n fi ojoojumọ ni iriri rẹ kuro lọwọ iṣẹ eṣu, iṣẹ ẹṣẹ ati itanjẹ aye yi. Idi niyi ti Pọọlu ṣe sọrọ nipa awọn ti o n ṣegbe ati awọn ti a n gbala (1Kọ́ríntì 1:18; 2Kọ́ríntì 2:15).
Ṣe o ri, niwọn igba ti eniyan ba si wa laaye, a ko le sọ wipe o ti ṣegbe, bi ko tilẹ ti gba Jesu gbọ ni Oluwa ati Olugbala rẹ. O si n ṣegbe ni. Igba ti o ba ku sinu ipo aigbagbọ rẹ ni a to le sọ wipe o ti ṣegbe. Nibakanna, niwọn igba ti eniyan ba si wa laaye, iriri igbala rẹ ko i ti pari. Idi si ni pe eṣu, ẹṣẹ, aye ati ẹran-ara yoo si ma gbogun ti lati doju igbagbọ rẹ dele. Ṣugbọn, gẹgẹ bi Peteru ti jẹ ki o ye wa ninu awọn ẹṣẹ lẹta rẹ ti o wa loke yẹn, agbara Ọlọrun n pa irufẹ ẹni bẹẹ mọ si igbala nitori igbagbọ rẹ. Nitorina, dipo ki igbagbọ rẹ kuna nitori oniruuru idojukọ ti o n ba a pade, nṣe ni yoo ni okun si i, ti yoo si yọri si ogo ati ọla nigba ti Jesu Oluwa wa ba pada de.
Irufẹ igbala wo wa ni a n sọ nibẹyẹn? Igbala ayeraye ni. Jesu ti ṣiṣẹ igbala yi. Amọ, igba ti a ba to kuro ni aye yi ni a o to ni iriri igbala ayeraye yi kuro lọwọ ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu iṣẹ eṣu, ẹṣẹ, ẹran-ara ati aye. Niwọn igba ti a ba wa wa ninu aye yi, a gbọdọ ma fi igba gbogbo ṣe amulo oore-ọfẹ ati agbara Ọlọrun lati ri pe igbagbọ wa yọri si iriri igbala ayeraye yi (Fílípì 2:13).
Nkan ti a n sọ ni pe, bi o tilẹ jẹ wipe a ko ri Jesu soju ri, igbagbọ wa ninu rẹ ati ifẹ wa fun, eyi ti o n jẹ ki a fi ojoojumọ sin in, lere ti ko ṣe fẹnusọ lori. Peteru tilẹ tẹsiwaju lati jẹ ki o ye wa pe awọn wolii atijọ ti wọn sọ tẹlẹ nipa asiko oore-ọfẹ yi fẹ lọkan wọn lati tọ ọ wo, lati wa láàyè nigba ti yoo ṣeeṣe ki a tun eniyan bi. Bẹẹ si ni, o tun wu awọn angẹli pẹlu lati kopa ninu oore-ọfẹ ti a ni lati jẹ ajogun ohun gbogbo ti Ọlọrun ni ti ki i dibajẹ. (Wo: 1Pétérù 1:10-12)
Nitorina, a ko gbọdọ jẹ ki ẹnikẹni tan wa jẹ tabi gba igbagbọ wa danu kuro lọwọ wa. Dipo bẹẹ, Peteru sọ wipe nṣe ni o yẹ ki a ṣe ọkan wa giri lati gbe igbe aye iwa mimọ ati ikora-ẹni-nijanu ati lati fojusọna fun iriri igbala ayeraye wa ti yoo waye nigba ti Jesu Kirisiti Oluwa wa ba farahan. Ki a si ṣe eyi nipa fifiyesi awọn nkan wọnyi:
– Mímọ́ ni ẹni tí ó pè wá: Peteru, ninu lẹta yi sọ wipe, “Ṣugbọn gẹgẹ bi ẹni ti o pe yin ti jẹ mimọ; bẹẹ ni ki ẹyin naa jẹ mimọ. Nitori a ti kọ ọ pe, “Ẹ jẹ mimọ: nitori ti Emi jẹ mimọ!”” (1Pétérù 1:15-16) Ki ni itumọ eyi? Oun naa ni pe mimọ ni Ọlọrun Baba wa, ti O pe wa, ti O tun wa bi, ti O si ya wa sọtọ. Nitorina, ti a ba jẹ ọmọ rẹ nitootọ, igbe aye iwa mimọ ni a gbọdọ fi ara wa jin fun ninu aye eeri ati idibajẹ yi.
– Ọlọ́run yóò ṣe ìdájọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan: Idi keji ti a fi gbọdọ fi ara wa jin fun iwa mimọ ni pe Ọlọrun yoo ṣe idajọ ẹnikọọkan ti o gbe ile aye yi lọjọ kan. Ko si wa si ojuṣaaju pẹlu rẹ. Nitorina, ki a ma ro wipe a le pe ara wa ni ọmọ Ọlọrun, ki a si tun ma ṣe ohun ti o wu wa. Ẹni ti ko ba gbe igbe aye rẹ bi ọmọ Ọlọrun ko gbọdọ reti pe ki Ọlọrun fun ni ere ti o tọ si awọn ọmọ rẹ. (Wo: 1Pétérù 1:17)
– A ti ràwá padà àti tún wa bí: Nkan kẹta ti a gbọdọ fiyesi ni gbigbe igba aye iwa mimọ ni pe a ti ra wa pada kuro ninu igbe aye asan ti a jogun lati ọwọ awọn baba-nla wa. A si tun ti tun wa bi. Ki wa ni a fi ra wa pada lati ma gbe igbe aye asan mọ? Ṣe owo ni? Ṣe wura tabi fadaka ni? Rara! Ẹjẹ Jesu Kirisiti ti O ku fun wa ni a fi san gbese ẹṣẹ ati igbesi aye asan wa. Ki si ni a fi tun wa bi? Ṣe nipasẹ agbara ibi ti ẹran-ara ti o ma n dibajẹ tabi ku ni bi? Rara o! Nipasẹ ọrọ Ọlọrun, ọrọ iyinrere rẹ, ti ko ki i dibajẹ, ti a si ti fi waasu si wa, ni a fi tun wa bi. Nitorina, ti a ba n gbe igbe aye asan, igbe aye ẹṣẹ, igbe aye ikorira, nṣe ni a n fi han pe a ko i ti tun wa bi rara tabi wipe a ti gbagbe pe a ti di ẹni ọtọ. (Wo: 1Pétérù 1:18-25)
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Lakotan, koko nkan ti Peteru n fi idi rẹ mulẹ fun wa ni ori kini lẹta rẹ ni pe igbagbọ ninu Jesu Kirisiti lere, o n ṣiṣẹ si igbala ati ogun ayeraye. Nitorina, a ko gbọdọ fọwọ yẹnpẹrẹ mu igbagbọ naa, bi a tilẹ n dojukọ oniruuru igbogun eṣu, ẹṣẹ, ẹran-ara ati aye yi lojoojumọ. Dipo eyi, nṣe ni ki a duro ṣinṣin ninu rẹ ni ireti pe Jesu Oluwa wa yoo de lọjọ kan lati fun wa ni ẹkunrẹrẹ iriri igbala aye ati ọkan wa.
ÌBÉÈRÈ
– Kini o lero pe o n jẹ ki awọn angẹli naa fẹ tọ oore-ọfẹ ti a ni ninu Jesu wo?
– Kini o ṣe pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi?
Láti ọ́wọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2024 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07025105978)
ÀKỌ́RÍ: ÀGBÉLÉBÙÚ JÉSÙ | ÀYỌKÀ: JOHANU 19:16-37 | ỌJỌ́RÚ 26, IGBE 2023
ÀKỌ́SÓRÍ: ”A ti kan mi mọ agbelebu pẹlu Kirisiti: ṣugbọn mo wa laaye, sibẹ ki i ṣe emi mọ, ṣugbọn Kirisiti wa laaye ninu mi. Wiwa ti mo si wa laaye ninu ara, mo wa laaye ninu igbagbọ ọmọ Ọlọruin, eni ti o fẹ mi, ti o si fi ara rẹ fun mi.” (Galatia 2:20)
Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ
Kini itunmọ agbelebu Jesu? Ki lo fa ti O fi nilo lati ku iku ori agbelebu? Ọpọ awọn ọmọ Ọlọrun ni oye nkan ti agbelebu Jesu tunmọ si ko ye. Sibẹsibẹ, wọn a ma gbe ẹ̀gbà agbelebu kọ ọrun, wọn a ma fi ẹ̀gbà agbelebu si ọwọ, wọn si tun ma ṣe aami agbelebu ti wọn ba n gbadura tabi ti wọn ba n dupẹ lọwọ Ọlọrun. Awọn kan tilẹ ni ẹda agbelebu sinu ile wọn, ti wọn si n lo lati gbadura ati lati ṣe oniruuru nkan lati fi ara wọn lọkan balẹ ni asiko iṣoro. Ṣe awọn nkan wọnyi tọna tabi ko tọna? Oye ti a ba ni nipa agbelebu Jesu ati nkan ti o tunmọ si ni yoo sọ boya wọn tọna tabi wọn ko tọna. Idi si ni yi ti ẹkọ lori agbelebu Jesu ṣe ṣe pataki fun gbogbo awa ti a jẹ ọmọ Ọlọrun.
IKÚ JÉSÙ
Wayi o, ki ni idi ti a ṣe pa Jesu? A ko nilo lati ṣe aroye lọ titi lori nkan ti o fa ti a fi pa a. Nitori pe kedere ni a fi han ninu bibeli pe nitori ilara awọn adari ẹsin awọn Juu ni a ṣe kan mọ agbelebu. Lotitọ, oniruuru asọtẹlẹ ni a ti sọ nipa iku rẹ ki a to bi (Àpìsáyà 53; Mátíù 1:21; Lúùkù 24:25-27). Lafikun, nigba ti Johanu Onitẹbọmi bẹrẹ si ni waasu, ara awọn nkan ti o sọ ni pe Jesu ni ọdọ aguntan Ọlọrun ti o ko ẹṣẹ araye lọ (Jòhánù 1:29). Yatọ si eyi, Oun funrarẹ sọ asọtẹlẹ nipa iku rẹ ni ọpọ igba fun awọn ọmọ ẹyin rẹ ki o to di pe a pa a (Mátíù 16:21; Máàkù 8:31; Lúùkù 18:31). O tilẹ jẹ ki o ye wọn pe Oun mọọmọ fi ẹmi ara Oun lelẹ ni fun irapada araye ni (Jòhánù 10:11-18).
Amọ ṣa o, gbogbo awọn nkan ti a sọ yi ko jasi pe iku ẹlẹṣẹ ni Jesu ku. Jesu ko ku iku ẹlẹṣẹ. Jesu ko da ẹṣẹ rara. Iwo naa wo nkan ti O sọ fun awọn Juu ati awọn adari ẹsin wọn ni ọjọ kan: “Tani ninu yin ti o le da mi lẹbi ẹṣẹ? Bi mo ba n sọ otitọ eeṣe ti ẹyin ko fi gba mi gbọ?” (Jòhánù 8:46) A tun sọ eleyi nipa rẹ ninu iwe Heberu: “Nitori a ko ni olori alufaa ti ko le ṣai bani kẹdun ninu awọn ailera wa, ẹni ti a ti danwo lọna gbogbo gẹgẹ bi awa ṣugbọn oun ko dẹsẹ.” (Hébérù 4:15)
Yatọ si eyi, awọn ti o pa Jesu gan mọ ko ki i ṣe ẹlẹṣẹ. Wọn mọ pe nitori ilara ni awọn ṣe pa. Fun apẹẹrẹ, wo diẹ lara awọn nkan ti a sọ nipa Pilatu, ẹni ti o da ẹjọ iku fun Jesu:
“Pilatu beere lọwọ wọn wi pe, “Ṣe ẹyin n fẹ ki emi da ọba awọn Juu silẹ fun yin?” oun mọ pe nitori ilara ni awọn olori alufaa ṣe fa Jesu le oun lọwọ.” (Máàkù 15:9-10)
“Pilatu si tun jade, o si wi fun wọn pe, “Wo o, mo mu u jade tọ yin wa, ki ẹyin ki o le mọ pe, emi ko ri ẹṣẹ kan lọwọ rẹ.” (Jòhánù 19:4)
Nitorina, ko ki i ṣe nitori ẹṣẹ ni a ṣe pa Jesu. Sibẹsibẹ, a pa a. A pa a nitori ki ifẹ Ọlọrun fun irapada araye ba le wa si imuṣẹ. Amọ, ki lo wa fa a ti o ṣe jẹ pe iku ori igi agbelebu ni o ku? Ki ni o fa a ti a ko ṣe lo ọna miran lati pa a? Eyi gan ni o ṣe pataki ki awa gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun mọ, ki a ba le mọ iha ti o tọ fun wa lati kọ si oniruuru ẹkọ ti o n tan kalẹ lori agbelebu Jesu.
Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, iku Jesu lori igi agbelebu ni itunmọ ti o yatọ diẹ fun awọn Juu ati fun gbogbo eniyan lapapọ. Akọkọ naa, a gbọdọ fi si ọkan pe iku Jesu wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun, gẹgẹ bi a ti fi han ninu bibeli. Fun apẹẹrẹ, Pọọlu sọ eyi fun awọn ara Kọrinti nipa iku Jesu: “Nitori eyi ti mo ri gba ṣaaju ohun gbogbo ni emi pẹlu ti gba le yin lọwọ, bi Kirisiti ti ku nitori ẹṣẹ wa gẹgẹ bi iwe mimọ ti wi. Ati pe a sinku rẹ, ati pe o jinde ni ijọ kẹta gẹgẹ bi iwe mimọ ti wi…” (1Kọ́ríntì 15:3-4) Nitorina, iku Jesu, ajinde rẹ ati gbogbo nkan ti o ṣẹlẹ si ni asiko ti a pa a ni o wa ni ibamu pẹlu akọsilẹ Iwe mimọ, ti o si ni itunmọ.
Idi si ni yi ti Johanu, ọkan lara awọn ti o wa niwaju agbelebu Jesu ki o to ku, fi ri daju pe oun fi idi awọn nkan ti o ṣẹlẹ si ni asiko yi mulẹ ninu Iwe mimọ. Iwọ naa wo awọn nkan ti o kọ silẹ nipa rẹ:
“Nigba naa ni awọn ọmọ ogun, igba ti wọn kan Jesu mọ agbelebu tan, wọn mu aṣọ rẹ, wọn si pin wọn si ipa mẹrin, apakan fun ọmọ ogun kọọkan, ati ẹwu awọtẹlẹ rẹ, ṣugbọn ẹwu awọtẹlẹ naa ko ni ojuran, wọn hun un lati oke titi jade. Nitori naa wọn wi fun ara wọn pe, Ẹ ma jẹ ki a faa ya, ṣugbọn ki a ṣe gege nitori rẹ, yi ẹni ti yoo jẹ: Ki iwe-mimọ ki o le ṣẹ, ti o wi pe, “Wọn pin aṣọ mi laaarin ara wọn, wọn si ṣe gege fun aṣọ ileke mi.” Nnkan wọnyi ni awọn ọmọ ogun ṣe.” (Jòhánù 19:23-24)
“Lẹyin eyi, bi Jesu ti mọ pe a ti pari ohun gbogbo tan, ki iwe mimọ ba a le ṣẹ, o wi pe, “Orungbẹ n gbẹ mi.”” (Jòhánù 19:28)
“Ṣugbọn nigba ti wọn de ọdọ Jesu, ti wọn si ri i pe o ti ku, wọn ko ṣẹ egungun rẹ: Ṣugbọn ọkan ninu awọn ọmọ ogun naa fi ọkọ gun un lẹgbẹẹ, loju kan naa, ẹjẹ ati omi si tu jade. Ẹni ti o ri si jẹrii, otitọ si ni ẹri rẹ: o si mọ pe ootọ ni oun sọ, ki ẹyin baa le gbagbọ. Nnkan wọnyi ṣe, ki iwe mimọ ba a le ṣẹ, ti o wi pe, “A ki yoo fọ egungun rẹ.” Iwe mimọ miiran pẹlu si wi pe, “Wọn o maa wo ẹni ti a gun lọkọ.”” (Jòhánù 19:33-37)
Nitorina, iku Jesu ati awọn nkan ti o wọ tọ ọ ko ki i ṣe ṣababi rara – amuṣẹ awọn ọrọ inu iwe-mimọ nipa rẹ ni. Bi a ti ṣe gbe sinu iboji ọlọrọ ni, Josẹfu ara Arimatiya, gan an tun jẹ amuṣẹ ọrọ bibeli pẹlu, eyi ti o sọ wipe: “A fun un ni iboji pẹlu awọn ika, ati pẹlu awọn ọlọrọ ni iku rẹ, bi o tilẹ jẹ pe ko huwa jagidijagan kan, tabi ki a ri ẹtan kan ni ẹnu rẹ.” (Àísáyà 53:9)
Mo fi gbogbo awọn ẹṣẹ bibeli yi han wa lati jẹ ki o ye wa pe gbogbo nkan ti o sorọ mọ iku Jesu ni o ni itunmọ. Ki wa ni itunmọ iku rẹ lori agbelebu? Akọkọ naa, a ti ri siwaju pe akọsilẹ iwe-mimọ ni pe a ko ni ṣẹ egungun rẹ kankan lati pa a (Sáàmù 34:19-20). Idi ni ti a ko ṣẹ bẹ lori tabi ṣẹ egungun ọrun rẹ. Ṣugbọn awọn iku miran si wa ti ko nilo ka ṣẹ egungun eniyan. Iku majele wa. Iku omi naa si wa pẹlu. Ki wa lo de ti a ko fun Jesu ni majelẹ jẹ, tabi ki a sọ sinu omi tabi ki a lẹ ẹ lokuta pa, tabi ki a dana sun un? Idi ni pe awọn iku wọnyi ko ni mu ifẹ Ọlọrun fun irapada awọn Juu ati gbogbo araye ṣẹ. Wọn ko si tun ni mu ifẹ rẹ lori ajinde rẹ ninu ara ṣẹ.
ÌTUNMỌ̀ IKÚ ÀGBÉLÈBÚ FÚN ÀWỌN JÚÙ
Ki a ma fa ọrọ gun, Pọọlu ṣalaye fun wa idi ti Jesu fi nilo lati ku iku ori agbelebu fun wa ninu iwe rẹ si awọn ara Galatia. Wo nkan ti o sọ lori eyi:
“Nitori pe iye awọn ti n bẹ ni ipa iṣẹ ofin n bẹ labẹ egun: nitori ti a ti kọ ọ pe, “Ifibu ni olukuluku ẹni ti ko duro ninu ohun gbogbo ti a kọ sinu iwe ofin lati maa ṣe wọn.” Nitori o daniloju pe, a ko da ẹnikẹni lare niwaju Ọlọrun nipa isẹ ofin: nitori pe, olododo yoo ye nipa igbagbọ. Ofin ki i ṣi i ṣe ti igbagbọ: ṣugbọn “Ẹnikẹni ti n ṣe wọn yoo ye nipasẹ wọn.” Kirisiti ti ra wa pada kuro lọwọ egun ofin, ẹni ti a fi ṣe egun fun wa: nitori ti a ti kọ ọ pe, “Ifibu ni olukuluku ẹni ti a fi kọ sori igi.” Ki ibukun Aburahamu ba a le wa sori awọn alaikọla nipa Kirisiti Jesu: ki awa ba a le gba ileri Ẹmi nipa igbagbọ.” (Gàlátíà 3:10-14)
Kini Pọọlu n fẹ ki o ye wa pẹlu awọn nkan ti o sọ silẹ yi? O n fẹ ki o ye wa pe iku Jesu lori igi agbelebu wa fun irapada awọn Juu kuro labẹ egun ofin. Ofin wo? Ofin Mose! Gẹgẹ bi o ti tun fi ye wa, gbogbo awọn ti o wa ni abẹ ofin Mose, iyẹn awọn Juu, ni o wa ni abẹ egun. Irufẹ egun wo si ni yi? Egun ti o sọrọ mọ ikuna lati pa gbogbo ofin Mose mọ ni. Bi a ti ṣe kọwe rẹ, “Egun ni fun ọkunrin naa ti ko gbe ọrọ ofin yi ro nipa ṣiṣe wọn. Nigba naa ni gbogbo eniyan wọnyi yoo wi pe, “Amin!”” (Ditarónómì 27:26)
Ta wa ni o le pa gbogbo nkan ti a kọ sinu iwe ofin Mose mọ? Ko si ẹni naa. Nitorina, gbogbo awọn ti o wa ni abẹ ofin Mose ni o wa ni abẹ egun. Bawo wa ni iku Jesu ni ori agbelebu ṣe wa tan ọran yi? Bi Pọọlu ti ṣe fi ye, Jesu ni lati di ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu egun ofin Mose lati le ra awọn ti o wa ni abẹ ofin yi pada. Eyi gan si ni o ṣẹlẹ nigba ti o wa ni ori igi ti a kan an mọ. Bi a ti ṣe kọwe rẹ, “Bi ọkunrin kan ti o jẹbi ẹṣun ba n lati ku ti o si ku, ti a si gbe oku rẹ kọ sara igi, o ko gbọdọ fi oku rẹ silẹ sara igi ni gbogbo oru. Gbiyanju lati sin in ni ọjọ naa gan an, nitori ẹni ti a ba gbekọ sori igi wa labẹ egun Ọlọrun. O ko gbọdọ ba ilẹ ti Oluwa Ọlọrun rẹ fun ọ gẹgẹ bi ogun jẹ.” (Ditarónómì 21:23)
Nitorina, iku Jesu, ẹni ti ko ni ẹṣẹ rara, lori igi sọ ọ di egun fun gbogbo awọn Juu ti o wa ni abẹ ofin Mose. Eyi si jẹ ki irapada di ti wọn. Ẹnikẹni ti o ba wa tun n gbiyanju lati di ẹni itẹwọgba niwaju Ọlọrun nipa pipa ofin Mose mọ kan tun n fi ara rẹ si abẹ egun ni. Amọ ṣe oye eyi ye awọn adari ẹsin Juu ti wọn ditẹ titi ti a fi kan Jesu mọ agbelebu? Rara o! Oye rẹ ko ye wọn. Awọn kan fẹ ki o ku iku ti o buru julọ ni ilẹ wọn ni, iku ẹṣin, iku egun. Wọn ko mọ pe nipa iku yi, yoo di egun fun irapada gbogbo wọn kuro ni abẹ egun ofin Mose.
ÌTUNMỌ̀ IKÚ ÀGBÉLÈBÚ FÚN ÀWỌN GBOGBO ÈNÌYÀN
Wayi o, yatọ si pe iku Jesu lori igi agbelebu ṣiṣẹ fun itusilẹ awọn Juu kuro labẹ egun ofin, o tun ṣiṣẹ fun irapada gbogbo araye. Lọna wo? Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, Jesu ni ẹniti Ọlọrun fa kalẹ lati san gbese ẹṣẹ gbogbo araye. BI bibeli ṣe jẹ ki o ye wa, gbogbo wa patapata ni a ti ṣẹ lati ara Adamu, ti a si tu ku nipa ti ẹmi (Róòmù 3:23). Iku ti ẹmi yi ni i ṣe pẹlu iyapa kuro lọdọ Ọlọrun. Ọlọrun duro fun iye. Nitorina, ẹnikẹni ti o ba yapa kuro lọdọ rẹ yapa kuro lọdọ iye niyẹn – oku ninu ẹmi ni irufẹ ẹni bẹ ẹ si jẹ.
Ko wa tan sibẹ o. Iku ẹmi ti Adamu ku lẹyin ti o ṣe aigbọran si aṣẹ Ọlọrun ni o mu iku ti ara wa (Róòmù 5:12). Ṣugbọn, nitori ifẹ Ọlọrun si wa, gbogbo igba ni O ma n gbe igbesẹ lati sọ wa ji kuro ni ipo iku ti ẹmi, ti O si n ba wa laja, ki a ba le pada sọdọ rẹ. Ki si ni idi? Idi ni pe ẹnikẹni ti iku ti ara ba ba pade ni ipo oku ninu ẹmi si Ọlọrun ko tun ni ni ohunkun ṣe pẹlu Ọlọrun mọ titi ayeraye. Eyi ni a n pe ni iku ayeraye. Ohun si tun ni bibeli pe ni ijiya lẹkunrẹrẹ fun ẹṣẹ wa (Róòmù 6:23).
Ki a ma ba wa di ẹni iyapa kuro lọdọ Ọlọrun fun ayeraye ni O ṣe gbe igbesẹ lati san gbese gbogbo ẹṣẹ ti a ti da ati eyi ti a o da titi asiko aye yi yoo fi kasẹ nilẹ. Lọna wo? Nipa pipese eniyan bi ti wa, ẹni ti yoo jẹ aṣoju gbogbo wa lati san an. Angẹli ko le san gbese ẹṣẹ wa, nitori awọn kọ ni o dẹṣẹ, yatọ si pe wọn ko koju oṣuwọn. Bẹẹ si ni pẹlu, awọn ẹranko ko le san gbese ẹṣẹ wa, nitoripe awọn kọ ni o dẹṣẹ, yatọ si pe wọn ko joju oṣuwọn. Ọkan ti o ba dẹṣẹ naa ni o tọ lati ku iku ayeraye lati san gbese ẹṣẹ rẹ (Ìsíkíẹ̀lì 18:4).
Eyi wa jasi pe eniyan nikan naa ni o le san gbese ẹṣẹ rẹ. Ko wa jẹ dandan ki gbogbo eniyan ti o dẹsẹ ku ki a to san gbese ẹṣẹ wọn. Ẹnikan ṣoṣo ti to lati san gbese ẹṣẹ wọn. Idi si ni pe lati ara ẹnikan ni gbogbo eniyan ti wa, iyẹn Adamu. Lati ara ẹnikan ṣoṣo yi i naa si ni gbogbo awọn eniyan ti ṣe di ẹlẹṣẹ. Nitorina, ti a ba ri ẹnikan ti o koju oṣuwọn lati san gbese ẹṣẹ wọn, awọn yoku ko nilo lati san an mọ, niwọn igba ti wọn ba ti tẹwọgba iṣẹ ti ẹni naa ṣe fun wọn.
Ṣe a wa ri lara iru ọmọ eniyan ẹnikẹni ti o koju oṣuwọn lati jẹ aṣoju wọn ati lati san gbese ẹṣẹ wọn? A ko ri ẹni na, yala laye ni tabi ni ọrun tabi ni isalẹ ilẹ (Ìfihàn 5:1-4). Idi si ni pe ẹni naa gbọdọ jẹ alailẹṣẹ ati alailabawọn eniyan. Aijẹbẹ, iṣẹ itusilẹ rẹ fun wa ko ni jẹ itẹwọgba. Idi ni yi ti Ọlọrun fi ran Jesu, ọmọ rẹ, ti a bi nipasẹ obinrin ṣugbọn ti ko wa lati ara Adamu, wa saye. Oun nikan naa si ni ẹni ti o koju oṣuwọn niwaju Ọlọrun, ẹni ti inu Ọlọrun dun si gidigidi, lati ku fun ẹṣẹ wa. Idi si ni pe ko si ẹṣẹ tabi abawọn kan ninu aye rẹ (Hébérù 4:15 & 7:26).
Wo awọn ẹṣẹ bibeli wọnyi:
“Loootọ o ti farada ẹdun wa, o si ti gbe ibanujẹ wa lọ; ṣugbọn awa ka a si bi ẹmi ti a na, ti a lu lati ọdọ Ọlọrun, ti a si pọn loju. Ṣugbọn a ṣa a ni ọgbẹ nitori irekọja wa, a pa ni ara nitori aiṣedeede wa; ina alaafia wa wa lara rẹ, ati nipa ina rẹ ni a fi mu wa larada. Gbogbo wa ti ṣina kiri bi agutan, olukuluku wa tẹle ọna ara rẹ, Oluwa si ti mu aiṣedeede wa gbogbo pade lara rẹ.” (Àìsáyà 53:4-6)
“Ni ọjọ keji, Johanu ri Jesu n bọ wa sọdọ rẹ; o wi pe, Wo o, ọdọ agutan Ọlọrun, ẹni ti o ko ẹṣẹ aye lọ.” (Jòhánù 1:29)
“Gbogbo eniyan ni o ṣaa ti ṣẹ, ti wọ si kuna ogo Ọlọrun; Awọn ẹni ti a n da lare lọfẹẹ nipa oore-ọfẹ rẹ, nipa idande ti o wa ninu Kirisiti Jesu: Ẹni ti Ọlọrun ti gbe kalẹ lati jẹ etutu nipa igbagbọ ninu ẹjẹ rẹ, lati fi ododo rẹ han nitori idariji ẹṣẹ awọn ti o ti kọja, ninu ipamọra Ọlọrun; Lati fi ododo rẹ han ni igba isinsinyi: ki o le jẹ olododo ati oludalare ẹni ti o gba Jesu gbọ.” (Róòmù 3:23-26)
“Ẹni ti a jọwọ rẹ lati ku nitori awọn ẹṣẹ wa gbogbo, ti Ọlọrun si ji i dide kuro ninu oku lati ba awa ati Ọlọrun laja.” (Róòmù 4:25)
“Nitori ifẹ Kirisiti n dari wa, nitori awa ro bayii, pe, bi ẹnikan ba ti ku fun gbogbo eniyan, njẹ gbogbo wọn ni o ti ku.” (2Kọ́ríntì 5:14)
“Nitori o ti fi i ṣe ẹṣẹ nitori wa, ẹni ti ko mọ ẹṣẹkẹṣẹ ri; ki awa le di ododo Ọlọrun ninu rẹ.” (2Kọ́ríntì 5:21)
“Nitori ti Kirisiti pẹlu jiya lẹẹkan nitori ẹṣẹ wa, gẹgẹ bi oloootọ fun awọn alaiṣootọ, ki o le mu wa de ọdọ Ọlọrun, ẹni ti a pa ninu ara, ṣugbọn ti a sọ di aaye ninu ẹmi.” (1Pétérù 3:18)
“Ẹyin ọmọ mi, emi n kọ iwe nnkan wọnyi si yin, ki ẹ ma baa dẹṣẹ. Bi ẹnikẹni ba si dẹṣẹ, awa ni alagbawi lọdọ Baba, Jesu Kirisiti olododo. Ohun si ni etutu fun ẹṣẹ wa: ki i si i ṣe fun tiwa nikan, ṣugbọn fun ti gbogbo araye pẹlu.” (1Jòhánù 2:1-2)
Diẹ lara awọn abala tabi ẹsẹ bibeli ti o mẹnuba itumọ iku Jesu ni eyi. Nkan ti gbogbo wọn si n jẹ ki o ye wa ni pe Jesu ko ku lori igi agbelebu fun ara rẹ. Dipo bẹẹ, nṣe ni O ku fun ẹṣẹ gbogbo araye. Idi niyi ti a ṣe pe ni etutu fun ẹṣẹ wa. Eyi tunmọ si pe awa ni O n ṣoju nigba ti a kan an mọ agbelebu. Awa ni o n ṣoju nigba ti O ku, ti a si sin in. Awa kanna yi si tun ni O n ṣoju nigba ti a ji i dide kuro ni ipo oku. Pọọlu ṣalaye eyi nipa jijẹ ki o ye wa pe Jesu da ohun gbogbo ti a tipasẹ ẹṣẹ Adamu da, ki awa ba le da ohun gbogbo ti Oun tipasẹ Ọlọrun jẹ. (Wo: Róòmù 6:3-4)
Nitorina, ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu ijiya ẹṣẹ wa ni Jesu ti mojuto nipa iku rẹ. O ti mojuto iku ayeraye, iku ẹmi, iku ara, aisan, ìṣẹ́ ati ohun gbogbo ti o n fi eniyan si abẹ igbekun Eṣu. Yatọ si eyi, iku rẹ, ajinde rẹ ati igbasoke rẹ ni o jẹ ki Ọlọrun le sọ wa di ọmọ rẹ, ki O si tun fi Ẹmi Mimọ rẹ sinu wa lati ma gbe inu wa. Bẹẹni, iku rẹ ni o jẹ ki eniyan le di ti Ọlọrun pada gẹgẹ bi ẹni idalare ati olododo titi ayeraye. Ohun kan ṣoṣo ti a si nilo lati jẹ igbadun ere iku, ajinde ati igbasoke rẹ naa ni ki a gba a ni Oluwa wa. Ti a ba ti gba ni Oluwa wa, iṣẹ ti O ṣe fun igbala ọkan ati aye wa yoo di ti wa lati jẹ igbadun.
ÀMÌ ÀGBÉLÈBÚ
Bawo wa ni ti ami agbelebu ti awọn eniyan ma n ṣe ti ṣe jẹ? Ki ni iwulo rẹ? Ami agbelebu ko ni iwulo kankan, bi o ti wu ki o ri, fun igbala ọkan eniyan. Lotitọ, Jesu sọ eyi ki O to ku fun wa: “Bi Mose ti gbe ejo soke ni aginju, gẹgẹ bẹẹ ni a ko le ṣe alaigbe ọmọ-eniyan soke pẹlu: Ki ẹnikẹni ti o ba gba a gbọ, ki o ma baa ṣegbe, ṣugbọn ki o le ni iye ainipẹkun.” (Johanu 3:14-15) Ki ni itumọ eyi? A ri itumọ rẹ ninu ọrọ miran ti O tun sọ siwaju iku rẹ, eyi ti o ka bayi: “Ati emi, bi a ba gbe mi sokekuro ni aye, emi o fa gbogbo eniyan sọdọ ara mi. Ṣugbọn o wi eyi, o n ṣapẹẹrẹ iru iku ti oun yoo ku.” (Johanu 12:32)
Ṣe o ri bayẹn? Gbigbe Jesu soke ti O sọrọ nipa ni i ṣe pẹlu iku rẹ lori igi agbelebu. Wiwo Jesu wa n kọ? Ṣe wiwo lori igi agbelebu ni yoo jẹ ki a ni iye ainipẹkun bi? Rara o! Ọpọlọpọ eniyan ni o wo o nigba ti o wa lori igi agbelebu ti a kan an mọ. Ṣugbọn melo lara wọn ni o tipasẹ eyi di ẹni igbala? Awọn ti o gba a gbọ fun igbala wọn nikan ni o tipasẹ rẹ di ẹni igbala, ko ki i ṣe awọn ti o wo o lori igi.
Nitorina, wiwo Jesu ti o ku fun wa lori igi agbelebu ko tunmọ si pe ki a ranju mọ agbelebu ninu ọkan wa tabi pe ki a ma di agbelebu kaakiri tabi ki a fi agbelebu kan si yara wa lati ma wo. Ibọriṣa ni eyi jasi. Wiwo Jesu ni i ṣe pẹlu gbigbẹkẹle fun igbala wa ati ohun yowu ti a nilo lati gbe igbe aye ti o jẹ itẹwọgba niwaju Ọlọrun. Awa pẹlu ma n lo ede yi ti a ba n sọrọ nipa igbẹkẹle ninu eniyan. A ma n sọ pe, “Oju rẹ ni mo n wo o.” Eyi ko si tunmọ si pe a n ranju mọ ẹni naa tabi aworan tabi ere rẹ. Dipo bẹẹ, o tunmọ si pe a n fi igbẹkẹle wa sinu rẹ.
Yatọ si eyi, Jesu ko si lori igi agbelebu mọ. Ọwọ ọtun Ọlọrun Baba ni o wa bayi, ti O si n duro ki Ọlọrun fi gbogbo awọn ọta rẹ si abẹ ẹsẹ rẹ. Nitori naa, Jesu ti a sọ fun wa ki a wo ninu bibeli ko ki i ṣe Jesu ti O wa lori igi fun ẹṣẹ wa ṣugbọn Jesu ti a ji dide kuro ni ipo oku, ti O si wa ni ọwọ ọtun Baba, pẹlu gbogbo angẹli ati ohun gbogbo ti a da ni abẹ aṣẹ rẹ (Kolósè 3:1-2; 1Pétérù 3:21-22). Ko si wa si ibi ti a kọ silẹ si ninu bibeli pe ki a ma ṣe ami agbelebu iku rẹ tabi ẹda agbelebu iku rẹ fun igbala tabi aabo wa.
Ibo wa ni aṣa ki a ma ṣe ami agbelebu tabi ki a ma mu ẹda igi agbelebu kaakiri ti wa wa? O wa lati ọwọ awọn eke iransẹ Ọlọrun ti wọn fi ara wọn jin fun Satani lati lo wọn lati ṣi awọn ọmọ Ọlọrun lọna ati lati dari wọn sinu ibọriṣa. Gbogbo wọn ni yoo si gba idajọ ti o tọ si wọn ni Ọjọ Oluwa. Awa ni ki a wa mura wa giri, ki a si ma jẹ ki ẹnikẹni fi irọ ati ẹtan gba otitọ Kirisiti danu kuro lọwọ wa.
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Iku Jesu lori igi agbelebu ko ki i ṣe fun ara rẹ rara. Nṣe ni O ku fun igbala gbogbo araye, ni akọkọ, awọn Juu ti O ra pada kuro labẹ egun ofin ati, lẹyin rẹ, awọn Keferi ti O gba lọwọ ẹṣẹ wọn ati aṣa gbogbo ti o de wọn ni igbekun. Jesu ko wa si ni ipo oku mọ tabi ni ori agbelebu. A ti ji i dide. Eyi ni o si jẹ ki igbala ṣeeṣe. Ohun ti a kan nilo lati jẹ igbadun iṣẹ iku rẹ ni ki a gba a gbọ gẹgẹ bi Oluwa wa, ki a si jọwọ aye wa fun lati dari. Ohunkohun ti o ba wa yatọ si eyi, ti Eṣu ni.
IBEERE
– Ki ni o le pe ni aṣilo agbelebu Jesu?
– Bawo ni ẹkọ yi ṣe wulo si ni aarin awọn ọmọ Ọlọrun?
Lati ọwọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2024 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07025105978)
ÀKỌ́RÍ: KÍNI BÍBÉLÌ SỌ–Ọ̀ṢỌ́ ṢÍṢE | ÀYỌKÀ: 1TÍMÓTÌ 2:8-10 | ỌJỌ́RÚ 29, BELU 2023
ÀKỌ́SÓRÍ: “Bẹẹ gẹgẹ ni ki awọn obinrin ki o maa fi aṣọ iwọntunwọnsi ṣe ara wọn ni ọsọ, pẹlu itju ati iwa airekọja, kii ṣe pẹlu irun didi ati wura, tabi Piali, tabi aṣọ olowo iyebiye.” (1Tímótì 2:8)
Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ
Kini bibeli sọ lori ọsọ ara ṣiṣe? Ṣe o yẹ ki a mọ-ọn tabi ko yẹ ki a mọ-ọn? O yẹ ki a mọ-ọn. O yẹ ki a mọ-ọn nitoripe ọsọ ṣiṣe wa lara awọn nkan ti o n fa iyapa laarin awọn ọmọ Ọlọrun. Bi a ti ṣe mọ, awọn ọmọ Ọlọrun kan gbagbọ pe ko yẹ ki awọn ti o gba Jesu gbọ, paapaa julọ awọn obinrin, ma ṣe ọsọ ara wọn nipa lilo wura, fadakẹ tabi idẹ, yala si eti wọn ni, ọwọ wọn ni, imu wọn ni, ọrun wọn ni tabi ẹsẹ wọn. Awọn miran, ẹwẹ, si gbagbọ pe ko si nkan ti o buru ninu ki eniyan ṣe ọṣọ ara rẹ pẹlu awọn nkan ti Ọlọrun tikararẹ da fun lilo wa. Awọn wo wa ni ki a gbagbọ ninu wọn? Ki gan ni bibeli sọ lori ọrọ naa?
Ọ̀ṢỌ́ ṢÍṢE
Ti a ba wo bibeli daradara, a o ri wipe Ọlọrun ko lodi si ọṣọ ṣiṣe. Ki si ni id ti ko ṣe lodi si ọṣọ ṣiṣe? Akọkọ, ko lodi si nitoripe Oun ni o da gbogbo nkan ti a n lo laye yi, ti O si tun ko wọn le wa lọwọ fun lilo wa. Wo awọn nkan ti Pọọlu sọ nipa eyi:
“Nitori ohun gbogbo ti Ọlọrun da ni o dara, ko si ọkan ninu rẹ ti o yẹ ki akọ, bi a ba fi ọpẹ gba a.” (1Tímótì 4:4)
“Kilọ fun awọn ti n ṣe ọlọrọ ni aye nisinsinyi, ki wọn ma ṣe gberaga, bẹẹ ni ki wọn ma ṣe gbẹkẹle ọrọ wọn eyi ti ko daju, ṣugbọn ki wọn gbẹkẹle Ọlọrun alaaye, ti n fi ohun gbgbo fun wa lọpọlọpọ lati dun wa ninu.” (1Tímótì 6:17)
Njẹ o ri bayẹn? Gbogbo nkan ti Ọlọrun da patapata ni o dara. Niwọn igba ti a ba si ti fi ọkan ọpẹ gba awọn nkan ti O da wọnyi, yala wura ni, fadaka ni, idẹ ni, irin ni, ororo irara ni tabi owu, ẹnikẹni ko lẹtọ lati da wa lẹbi. Yatọ si iyẹn, a tun ri wipe gbogbo awọn nkan ti Ọlọrun da wọnyi sorilẹ aye ni O fi fun wa lati dun wa ninu. Niwọn igba ti eyi si ri bẹ ẹ, ko tọ fun ẹnikẹni lati da wa lẹjọ tabi lẹbi lori ohunkohun ti Ọlọrun da ti a n lo (Kólósè 2:20-23).
Idi keji ti Ọlọrun ko ṣe lodi si ṣiṣe ọṣọ pẹlu awọn nkan ti O da, iyẹn awọn nkan bi wura, fadaka, owu, idẹ abbl, bi a ti ṣe ri ninu bibeli ni wipe Oun funrarẹ sọ pe ki a ṣe Àgọ́ rẹ ati awọn alufa rẹ labẹ majẹmu atijọ lọsọ pẹlu awọn nkan wọnyi. Bẹẹ si ni pẹlu, Ọlọrun ko lodi si ki a lo wura, fadaka, idẹ ati awọn okuto iyebiye miran lati kọ Tẹmpili rẹ. Bi Dafidi tilẹ ṣe sọ, Ẹmi Mimọ gan an ni O kọ ni ohun gbogbo ti o la kalẹ lori bi a o ti ṣe kọ Tẹmpili Ọlọrun ti Jerusalẹmu ati awọn nkan wura, fadaka, idẹ abbl ti a o lo lati kọ ati ninu rẹ. (Wo: Ẹ́kísódù 25-28; 11Kíróníkà 28:11-19)
Yatọ si eyi, a tun ri wipe nigba ti Ọlọrun n ṣe apejuwe bi Oun ti ṣe n ṣe eniyan ni ọṣọ ni awọn abala bibeli kan, O lo awọn nkan bi wura, idẹ, fadaka abbl lati ṣe wọn ọṣọ. Siwaju si, a ri wipe lati ṣe ilu Jerusalẹmu ayeraye ti a n reti lọsọ, a fi han wa ninu bibeli pe Ọlọrun lo awọn nkan bi wura, fadaka ati oniruuru okuta iyebiye. Jesu Oluwa wa gan, bi Johanu ti ṣe ri ninu ifihan ti a fun un, lo amuro wura. Niwọn igba ti awọn nkan wọnyi si ri bẹ, ko yẹ ki a ro wipe Ọlọrun lodi si ṣiṣe ọsọ ara wa pẹlu wura, fadaka, idẹ, atike, oṣun abbl. (Wo: Ìsíkíẹ̀lì 16:1-14; Ifihan 1:12-13; Ìhihàn 21)
Ki wa lo fa ti awọn kan fi sọ wipe o lodi si ifẹ Ọlọrun ki awọn eniyan rẹ ma ṣe ọsọ ara wọn? Awọn miran tilẹ tako ṣiṣe ọṣọ ara debi wipe wọn a ma gbe oju agan si awọn ti o n lo ororo ikunra tabi itusara. Nkan akọkọ ti o fa ni aṣitunmọ ọrọ Ọlọrun. Nkan ti a n sọ ni pe awọn abala ọrọ Ọlọrun kan wa ti awọn eniyan ma n ṣi tunmọ lati fi idi ero ọkan wọn lori ṣiṣe ọsọ ara mulẹ. Fun apẹrẹ, wo abala bibeli yi:
“Nigba naa ni Ọlọrun wi fun Jakọbu pe, “Goke lọ si Bẹtẹli ki o si tẹdo sibẹ, ki o mọ pẹpẹ nibẹ fun Ọlọrun to farahan ọ nigba ti o n sa lọ kuro niwaju Isọ arakunrin rẹ.” Nitori naa, Jakọbu wi fun gbogbo ara ile rẹ pe, “Ẹ mu gbogbo ajoji orisa ti o wa lọdọ yin kuro, ki ẹ ya ara yin si mimọ, ki ẹ si paarọ aṣọ yin. Nigba naa ni ki ẹ wa, k iẹ jẹ ki a lọ si Bẹtẹli, nibi ti n o ti mọ pẹpẹ fun Ọlọrun, ti o da mi lohun ni ọjọ ipọnju mi ti o si ti n pẹlu mi nibi gbogbo ti mo n lọ.” Bẹẹ ni wọn fun Jakọbu ni gbogbo ajoji oriṣa ti o wa lọwọ wọn, ati yẹti eti wọn, Jakọbu si bo gbogbo wọn mọlẹ sabẹ igi Oaku ni Ṣekemu.” (Jẹ́nẹ́sísì 35:1-4)
Kini a ri ninu awọn ẹṣẹ bibeli yi? Oun naa ni wipe a ko le sin Ọlọrun pẹlu oriṣakorisa. Bi o tilẹ jẹ wipe Jakọbu jẹ olusin Ọlọrun, awọn ara ile rẹ, awọn iyawo rẹ ati awọn oṣiṣẹ rẹ ko mọ Ọlọrun bi o ti ṣe mọ-ọn. Nitorina, wọn ni awọn oriṣa ti wọn n bọ, ti wọn si tun n ko kaakiri pẹlu wọn si ibikibi ti wọn ba n lọ. Yatọ si eyi, lati ayedaye ni ọpọ awọn ti o n bọriṣa ti gba wipe awọn ọriṣa kan ni o da tabi ni o ni awọn nkan ti a n lo kan bi wura, fadaka, idẹ, irin, epo abbl. Idi niyi ti awọn kan fi gba laarin awọn Yoruba pe ogun ni oriṣa irin. Wọn a si titori eyi ma fi ọwọ wọ irin ati ohunkohun ti a ba fi irin ṣe. (Wo: Daniẹli 5:1-4)
Nitorina, nigba ti Jakọbu sọ fun awọn eniyan rẹ pe oun fẹ lọ tẹ pẹpẹ si Ọlọrun ni Bẹtẹli ati wipe wọn nilo lati ko gbogbo oriṣa wọn fun un, ko ki i ṣe kiki awọn oriṣa wọn ni wọn ko fun un – wọn tun ko gbogbo awọn nkan ti o ni i ṣe pẹlu ijọsin awọn oriṣa wọnyi fun un pẹlu. Idi niyi ti awọn yẹti eti wọn fi wa lara awọn nkan ti wọn ko fun un. Eyi ko wa jasi pe wọn ko tun lo yẹti mọ lati igba naa. Lati wa ma lo abala bibeli yi lati sọ wipe abọriṣa ni ẹnikẹni ti o ba n lo yẹti, ẹgba ọrun tabi awọn nkan miran ti a fi n ṣe ọṣọ ara tabi wipe iru ẹni bẹ n lọ si ọrun apadi jẹ aṣitunmọ ọrọ Ọlọrun. Nṣe ni o dabi pe ki a sọ wipe ẹnikẹni ti o ba n wa ọkọ n bọ ogun nitoripe irin ni a fi ṣe e tabi pe ẹnikẹni ti o ba n lo epo lati ṣe ọbẹ n bọ eṣu.
Amọ ti awọn eniyan ba ni awọn nkan ti o ni i ṣe pẹlu ibọriṣa tẹlẹ, ti wọn si woye pe ki awọn da wọn sigbo tabi dana sun wọn nitori pe wọn ti gba Jesu gbọ, ko si nkan ti o buru nibẹ. Tabi boya lilo awọn nkan wọnyi N RAN WỌN LETI IPA TI WỌN TI KO NINU IBỌRIṢA TABI NINU IṢẸ AṢEWO ṢIṢE SẸYIN ni wọn ṣe fẹ kọ wọn silẹ, deede ni. Ṣugbọn a gbọdọ mọ wipe ohun gbogbo ti a n lo laye yi, pẹlu awọn nkan ti awọn eniyan fi n mọ ere, jẹ ti Ọlọrun. Nitorina, bi a tilẹ ti lo awọn nkankan fun ibọriṣa tẹlẹ, niwọn igba ti a ba ti ya awọn nkan wọnyi sọtọ fun Ọlọrun, wọn ti di ohun elo fu ogo rẹ niyẹn. (Wo: Jóṣúà 6:15-19; Ìṣe Àpọ́sítélì 19:18-20)
Tun wo ẹsẹ bibeli yi:
“Nigba ti awọn eniyan naa si gbọ ihin buburu yii wọn kaanu: ko si si ẹnikan ti o wọ ohun ọsọ rẹ. Oluwa si ti wi fun Mose pe, wi fun awọn ọmọ Isiraẹli pe, ọlọ́rùn lile ni yin: bi emi ba goke wa saarin rẹ ni iṣẹju kan, emi o si run ọ: njẹ nisinsinyi bọ ohun ọsọ rẹ kuro lara rẹ, ki emi ki o le mọ ohun ti emi o ṣe si ọ.” (Ẹ́kísódù 33:5)
Ki ni idi ti awọn ọmọ Isiraẹli ko fi wọ awọn nkan ọṣọ wọn ni ọjọ ti a sọrọ rẹ yi? Idi ni wipe Ọlọrun n binu si wọn lọwọ. Ki lo si fa ibinu rẹ? Ibọriṣa wọn ni. Bi a ti ri ninu akọsilẹ bibeli, nitoripe wọn ko le mu suuru fun Mose lati ṣetan lọdọ Ọlọrun ti O n ba sọrọ, wọn da awọn nkan ọsọ wọn ti o jẹ wura jọ fun Aaroni lati mọ ere wura fun wọn. Eyi si bi Ọlọrun ninu gidigidi. Idi wa ni yi ti O fi sọ fun wọn pe ki wọn bọ ohun ọṣọ ara wọn kuro ki Oun tilẹ to sọ nkan ti Oun yoo ṣe fun wọn. (Wo: Ẹ́kísódù 32)
O wa ṣeni laanu pe awọn kan ti ka eyi si pe Ọlọrun ko fẹ ki awọn eniyan rẹ ma lo nkan ọsọ rara ki wọn ma ba bọ oriṣa. Ṣugbọn aṣitumọ bibeli ni eyi. Idi si ni pe, ni akọkọ, Ọlọrun ko ni ki wọn bọ awọn nkan ọsọ wọn danu. O kan ni ki wọn ko wọn si ẹgbẹ kan na ni. Ekeji, Ọlọrun funrarẹ gan ni O ni ki wọn gba awọn nkan ọṣọ yi lọwọ awọn ara Ijibiti nigba ti wọn n kuro ni ilẹ wọn (Ẹ́kísódù 3:21-23). Ẹkẹta, Ọlọrun pada sọ fun wọn pe ki wọn mu wa lara awọn nkan wọnyi lati ta Oun lọrẹ fun kikọ Agọ rẹ si aarin wọn (Ẹkisodu 25&35). Nitorina, aṣitumọ ọrọ Ọlọrun gba a ni lati sọ wipe o lodi si ifẹ Ọlọrun lati ma lo awọn ohun elo wura, fadaka, idẹ abbl lati ṣe ọsọ ara ẹni.
Nkan pataki miran ti o tun fa ti a ṣe ri awọn ọmọ Ọlọrun ti o gbagbọ pe o lodi si ifẹ Ọlọrun ki awọn eniyan ma ṣe ọṣọ ara wọn pẹlu awọn nkan elo wura, fadaka abbl ni oniruuru iran ti awọn kan sọ wipe awọn ri, ninu eyi ti a ti fi ye wọn pe inu ina ọrun apadi ni awọn ti o ba n lo awọn nkan wọnyi lati ṣe ọsọ ara wọn n lọ. Iha wo ni o wa yẹ ki a kọ si irufẹ awọn iran bi eyi? Iha ti ọrọ Ọlọrun ni ki a kọ si wọn naa ni a gbọdọ kọ si wọn.
Ọrọ Ọlọrun ti jẹ ki o ye wa pe iran kankan ko koju osuwọn ju ọrọ Ọlọrun lọ. Nitorina, irankiran ti o ba ti ta ko ọrọ rẹ jẹ eyi ti a gbọdọ gbe sọnu. A ko gbọdọ kọbiara si rara. Wo nkan ti Pọọlu sọ nipa eyi:
“Nisinsin yii, emi n tẹnumọ ọ pe ni igba ikẹyin awọn miiran yoo kuro ninu igbagbọ, wọn yoo maa fiyesi awọn ẹmi ti n tannijẹ, ati ẹkọ awọn ẹmi eṣu.” (1Tímótì 4:1)
“Ẹ ma ṣe jẹ ki ẹnikẹni ti o ni inu didun ninu irẹlẹ eke ati bibọ awọn angẹli lọ ere yin gba lọwọ yin, ẹni ti n duro lori nnkan wọn-ọn-ni ti o ti ri, ti o n ṣe fefe asan nipa ero ọkan ara rẹ. Ti ko si di ori ni ku ṣinṣin, lati ọdọ ẹni ti a n ti ipa orikee ati iṣan pese fun gbogbo ara, ti a si n so o ṣọkan pọ, ti o si n dagba nipa imisi Ọlọrun.” (Kólósè 2:18-19)
Ki ni awọn ẹṣẹ bibeli yi n fi ye wa? Akọkọ naa ni pe awọn emi eṣu, awọn ẹmi atanijẹ wa. Ekeji ni pe awọn ẹmi yi a ma kọ awọn onigbagbọ naa lati lodi si ifẹ Ọlọrun. Lọna wo? Ara awọn ọna ti wọn ma n lo ni aṣitunmọ iwe mimọ, iran eke, ala eke, isọtẹlẹ eke, iṣẹ iyanu eke ati ifarahan awọn angẹli eṣu ti wọn n ṣe bi angẹli imọlẹ. Pọọlu wa jẹ ki o ye wa pe ẹnikẹni ti o ba pe ara rẹ ni ọmọ Ọlọrun ti o wa gbe igbagbọ rẹ lori awọn iran, ala tabi ifarahan awọn angẹli ti o ri dipo ọrọ Ọlọrun ti ya ara rẹ kuro ninu Kirisiti. Nitorina, bi o ti wu ki o ṣe fefe to pẹlu ọrọ ẹnu rẹ, a ko gbọdọ kọbiara si nkan ti o n sọ, niwọn igba ti ko ba ti ba ọrọ bibeli mu.
Ṣe bibeli gan tilẹ wa sọ nkankan nipato lori ọsọ ṣiṣe ati iha ti o yẹ ki a kọ si? Bẹẹni! Amọ ṣa o, o ṣe pataki ki a ma lọ ọrọ rẹ lọrun tabi ṣi tunmọ, eyi ti ọpọ si n ṣe ni oni. Ki wa ni ọrọ rẹ sọ? Wo awọn ẹsẹ bibeli wọnyi:
“Bẹẹ gẹgẹ ni ki awọn obinrin ki o maa fi aṣọ iwọntunwọnsi ṣe ara wọn ni ọsọ, pẹlu itiju ati iwa airekọja, kii ṣe pẹlu irun didi ati wura, tabi Piali, tabi aṣọ olowo iyebiye. Bi ko ṣe nipa iṣẹ rere (eyi ti o yẹ fun awọn obinrin ti o jẹ olufọkansin Ọlọrun).” (1Tímótì 2:8-10)
“Ki ọṣọ yin ma ṣe jẹ ọṣọ ode, ti irun didi, ati wura lilo, tabi ti aṣọ wiwọ; Ṣugbọn ki o jẹ ẹni ti o farasin ni ọkan, ninu ọsọ aidibajẹ ti ẹmi irẹlẹ ati ẹmi tutu, eyi ti i ṣe iyebiye niwaju Ọlọrun. Nitori bayii ni awọn obinrin mimọ igbaani pẹlu, ti wọn gbẹkẹle Ọlọrun, fi ṣe ara wọn lọṣọọ, wọn a maa tẹriba fun awọn ọkọ tiwọn. Gẹgẹ bi Sara ti gbọ ti Aburahamu, ti o n pe ni oluwa rẹ. Ọmọbinrin ẹni ti ẹyin jẹ, bi ẹyin ba n ṣe rere, ti ohunkohun ko si dẹruba yin.” (1Pétérù 3:3-4)
Ki ni a ri dimu ninu awọn nkan ti a kọ silẹ ninu bibeli yi lori ọsọ ṣiṣe, paapaa julọ laarin awọn obinrin onigbagbọ? Awọn naa ni iwọnyi:
– Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì: A o ri wipe ko si ibi ti Pọọlu ati Peteru ti sọ ninu awọn ẹṣẹ bibeli yi pe ki awọn eniyan, paapaa julọ awọn obinrin wa ninu ijọ Ọlọrun, ma ṣe ọsọ rara. Dipo eyi, nkan akọkọ ti wọn fẹ ki a fi sọkan ni pe ọṣọ wa gbọdọ jẹ iwọntunwọnsi. Akọkọ, eyi jasi pe a ko gbọdọ ṣe ọsọ ti yoo jẹ ki awọn eniyan ma kọ ‘Hahaha’ si wa. A o ri pe lo ki i ṣe lilo nkan wura ati piali lati ṣe ọṣọ nikan ni Pọọlu ati Peteru mẹnuba. Wọn tun sọrọ nipa didi irun ati wiwọ aṣọ olowo iyebiye naa. Ṣe o wa jasi pe ki awọn obinrin wa ma di irun mọ tabi wọn aṣọ ti o dara mọ ni? Rara o. Nkan ti wọn n jẹ ki o ye wa ni pe yala irun ni a di ni, aṣọ ni a wọ ni tabi wura ni a lo, a gbọdọ jẹ ki o mọ niwọn – ki a ma ti AṢEJU bọ ọ. Eyi si tun wa jasi pe a ko gbọdọ jẹ ki ọsọ ṣiṣe sọ wa di ALAINIKANṢE TABI ALAIWULO. Aijẹbẹ, yoo pa ijẹri igbagbọ wa lara. Ọpọ lo si jẹ wipe akoko ati owo ti wọn n lo lati ṣe ọsọ ara wọn ti pọ ju. Ko si jẹ ki wọn wulo bi o ti ṣe tọ ati bi o ti ṣe yẹ fun awọn ẹbi wọn, ni ibi iṣẹ wọn tabi ninu ijọ Ọlọrun. Irufẹ awọn wọnyi si n lodi si ifẹ Ọlọrun fun aye wọn.
– Ọ̀sọ́ òde: Nkan miran ti Pọọlu ati Peteru tun jẹ ki o yẹ wa ninu awọn ẹṣẹ bibeli yi ni pe ọṣọ wa gbọdọ kọja ọsọ ode. Iwa mimọ, iṣẹ rere, iwa tutu, irẹlẹ, itẹriba ati imọwọn-ara-ẹni ni o yẹ ki o leke awọn nkan ti a fi n ṣe ọsọ. O wa ṣeni laanu pe nkan ti ọpọ awọn ọmọ Ọlọrun ti wọn n ṣe ọṣọ mọ, lọkunrin ati lobinrin, ko ju ọṣọ ode lọ. Wọn ko mọ wipe lalai ṣi ifarahan iwa rere ati iwa ododo ninu aye wọn, gbogbo ọsọ ti wọn n ṣe ko jamọ nkankan niwaju Ọlọrun.
Yatọ si awọn nkan meji pataki wọnyi, bibeli tun jẹ ki o ye wa pe a ko gbọdọ jẹ ki ọṣọ ṣiṣe fa awọn nkan wọnyi sinu aye wa tabi aye awọn miran:
– Àníyàn: Ti a ko ba ṣọra wa, aini awọn nkan ti a le fi ṣe ọṣọ bi o ti wu wa le di aniyan si wa lọrun. O le di nkan ti a o ko le ori ọkan wa tabi ti a o ma titori rẹ ka ori sinu. Eyi si le jẹ ki a ti ọwọ bọ nkan ti ko yẹ ki a ti ọwọ bọ. Idi niyi ti Jesu Oluwa wa ṣe sọ eyi fun wa: “Nitori naa, mo wi fun yin, ẹ ma ṣe ṣe aniyan nipa ẹmi yin, ohun ti ẹ o jẹ ati eyi ti ẹ o mu; tabi nipa ara yin, ohun ti ẹ o wọ. Ṣe ẹmi ko ha ṣe pataki ju ounjẹ lọ tabi ara ni ko ha ṣe pataki ju aṣọ lọ.” (Mátíù 6:25) Njẹ o ri bayi? Ẹmi wa ati agọ ara wa ṣe pataki si Ọlọrun ju ọṣọ ara lọ. Nitorina, a ko gbọdọ jẹ ki airi ọsọ ara ṣe bi a ti ṣe fẹ sọ wa di idakuda.
– Ibọriṣa: Bi a tun ti ṣe ri ninu bibeli, ohunkohun ti o ba n ṣe akoso aye eniyan ni Ọlọrun rẹ (2Pétérù 2:19). Ti a ba wa fi aye gba ifẹ ọṣọ ṣiṣe lati gba isakoso aye wa, ti a ko kọ iye ti a ko le awọn nkan ti a n fi n ṣe ọṣọ lori tabi ti o ni wa lara lati jọwọ wọn fun Ọlọrun lati lo tabi lati fi ṣe awọn miran ni aanu, a jẹ wipe awọn nkan ti a fi n ṣe ọṣọ yi ti di ọlọrun wa niyẹn. Pọọlu sọ wipe, “Ohun gbogbo ni o yẹ fun mi lati ṣe, ṣugbọn kii ṣe ohun gbogbo ni o ni ere: ohun gbogbo ni o yẹ fun mi lati ṣe, ṣugbọn emi ki yoo ṣe ẹru ohunkohun.” (1Kọ́ríntì 6:12) Eyi tunmọ si pe, bi o tilẹ ṣe wipe ko si ohun ti o buru ninu ki a ṣe ọsọ ara wa, a ko gbọdọ ṣọ ara wa di ẹru ọṣọ ṣiṣe. Eyi jasi pe a gbọdọ mọ igba ti ko pan dandan ki a lo ohunkohun lati ṣe ọṣọ, ki a si ṣetan lati ma lo ni asiko naa. Aijẹbẹ, a ti di ẹru ọṣọ ṣiṣe ati abọriṣa. Ọrọ Ọlọrun si sọ fun wa pe ki a sa fun ibọriṣa (1Jòhánù 5:21).
– Ikọsẹ: Nkan miran ti ọrọ Ọlọrun tun fẹ ki a kiyesi lori ọṣọ ṣiṣe ni ki o ma jẹ ohun ikọṣẹ tabi ipalara fun awọn miran. Lọna wo? Lati aṣa de aṣa, ọṣọ ṣiṣe ma n yatọ si ara wọn. Fun apẹrẹ, a sọ eleyi nipa awọn ara Midiani igba aye Gideoni: “O si wi pe, “Mo ni ẹbẹ kan ti mo fẹ bẹ yin ki ẹnikọọkan yin fun mi ni yẹti kọọkan lati mu ohun ti ọkan yin lati inu ikogun.” (Aṣa awọn ara Iṣimaili ni lati ma fi yẹti wura seti.)” (Onídàjọ́ 8:24) Eyi jasi pe ti ọkunrin Kirisitiẹni ba wọ yẹti si eti rẹ laarin awọn ara Iṣimaili, wọn ko ni ka si babara tabi si nkan ti ko tọ. Ṣugbọn ti o ba ṣe bẹẹ ni ibomiran, yala ni awọn ibi ti wọn ti ka awọn ọkunrin ti o n ṣe bẹ gẹgẹ bi oniranu tabi ni awọn ibi ti wọn ti ka wọn si abọriṣa, wọn le ma fi oju ire wo o. Nitorina, ni ibikibi ti a ba wa, a gbọdọ mọ ọṣọ tabi oge ṣiṣe ti o jẹ itẹwọgba (ti ko si tako ifẹ Ọlọrun) ati eyi ti ko jẹ itẹwọgba (bi ko tilẹ tako ifẹ Ọlọrun). Aijẹbẹ, a le mu ki awọn kan kọṣẹ tabi gan orukọ Jesu nipaṣẹ ọṣọ tabi oge ṣiṣe wa. Ọrọ Ọlọrun si wa si ni pe, “Nitori naa, ẹ jẹ ki a ye da ara wa lẹjọ. Dipo bẹẹ, ẹ pinu ninu ọkan yi lati ma ṣe fi okuta idigbolu kankan si ọna arakunrin yin.” (Róòmù 14:13) Nitorina, a ko gbọdọ jẹ ki ọṣọ ṣiṣe wa fi aye silẹ fun ikọṣẹ ẹnikẹni tabi fun isọrọ-odi si orukọ Jesu.
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Ọṣọ ṣiṣe ko ki i ṣe nkan tuntun rara. Lati ayebaye ni awọn eniyan ti n ṣe. Yatọ si eyi, Ọlọrun gan ni O pese gbogbo awọn nkan ti a n lo lati ṣe ọṣọ fun wa. Nitorina ko lodi si ifẹ rẹ fun wa lati ṣe ọsọ ara wa. Amọ, o ṣe pataki ki a ri daju pe a ko jẹ ki ọṣọ ṣiṣe wa sọ wa di idakuda, mu ẹrẹ ba orukọ Jesu tabi fa ikọsẹ fun ẹnikẹni. Ṣiṣe eyi lodi si ifẹ Ọlọrun fun aye wa.
ÌBÉÈRÈ
– Bawo ni ẹkọ yi ṣe ran imọ rẹ lọwọ si lori oge ṣiṣe?
Láti ọwọ́ Johnson O. Lawal
Copyright © 2023 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07025105978)
ÀKỌ́RÍ: KÍNI BÍBÉLÌ SỌ–ṢÒKÒTÒ WÍWỌ̀ FÚN OBÌNRIN | ÀYỌKÀ: DITARÓNÓMÌ 22:5 | ỌJỌ́RÚ 22, BELU 2023
ÀKỌ́SÓRÍ: “Nitori naa ẹ ma ṣe jẹ ki ẹnikẹni ṣe idajọ yin ni ti jijẹ, tabi ni ti mimu, tabi ni ti ọjọ aṣẹ, tabi oṣu titun, ati ọjọ isinmi: Awọn ti i ṣe ojiji ohun ti n bọ; ṣugbọn Kirisiti ni ara.” (Kólósè 2:16-17)
Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ
Lara awọn nkan ti o ma n fa ariyanjiyan laarin awọn onigbagbọ ninu Kirisiti ni ọrọ lori ṣokoto wiwọ fun obinrin. Eyi tilẹ ti fa iyapa ti o lagbara ni ọpọlọpọ ibi ti awọn ọmọ Ọlọrun wa, ti ko si jẹ ki awọn miran lara wọn le bara wọn ṣepọ lọna ti o yẹ gẹgẹ bi onigbagbọ. Njẹ o wa tọna ki obinrin Kirisitiẹni ma wọ ṣokoto tabi ko tọna? Awọn abala kan lara wa gbagbọ pe ko tọna rara, nigba ti awọn abala miran lara wa si wo pe ni awujọ nikan ni ko ti tọna – o tọna ninu ile. Awọn abala miran lara wa, ẹwẹ, woye pe ko si nkan ti o buru ninu ki obinrin wọ ṣokoto – imura ti o da lori aṣa lasan ni. Ewo ni ki a wa gbagbọ ninu awọn nkan ti a sọ silẹ yi? Kini bibeli sọ gan lori ọrọ naa? Eyi ni a fẹ gbeyẹwo ninu ẹkọ bibeli yi. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ṣi ilẹkun ọkan wa lati tẹwọgba nkan ti ọrọ rẹ so lori ọrọ yi fun igberusi wa ninu irin ajo igbagbọ wa. Amin.
ṢÒKÒTÒ WÍWỌ̀ FÚN OBÌNRIN
Bi mo ti ṣe sọ siwaju, ariyanjiyan ti o lagbara ma n ṣaba waye laarin awọn ọmọ Ọlọrun lori boya o tọna fun obinrin Kirisitiẹni lati ma wọ ṣokoto tabi ko tọna. A si wa ri wipe oye nkan ti ọrọ Ọlọrun sọ lori rẹ ko ye ọpọ rara. Idi si niyi, nigba miran, ti a fi ma n ri lara awọn obinrin ti o wa ninu ijọ ti wọn ko ti fọwọsi pe ki obinrin ma wọ ṣokoto ti wọn n wọ ṣokoto ni ile wọn, ni ibi iṣẹ wọn tabi ni awujọ wọn. Oye ọrọ yi ko ye awọn wọnyi. O si tun wa ṣeni laanu pe awọn ti o paṣẹ fun wọn pe ki wọn ma wọ ṣokoto naa ko ni alaye ti o munadoko, ti o si ṣe e tẹwọgba fun wọn lori ọrọ naa. Ọpọ igba ni o tilẹ jẹ wipe agidi ni irufẹ awọn adari ijọ bẹ ma n lo dipo ti wọn yoo fi ṣalaye bi ọrọ ti ṣe jẹ ati ifẹ Ọlọrun lori rẹ. Niwọn igba ti eyi ba si tẹsiwaju lati ma ri bẹ, a ko ni ṣe alairi awọn obinrin ti wọn yoo ma wuwa aibikita si nkan ti awọn adari ijọ wọn n sọ lori ọrọ ki obinrin wọ ṣokoto tabi ki o ma wọ ọ.
Nibo wa gan ni ọran yi ti ṣẹ? Ṣe lotitọ ni Ọlọrun pa a laṣẹ pe ki obinrin ma wọ ṣokoto? Nibo ni Ọlọrun ti pa a ni aṣẹ, ti o ba jẹ wipe O pa a laṣẹ nitootọ? Kini idi ti O ṣe pa a ni aṣẹ? Iha wo si ni o yẹ ki a kọ si aṣẹ rẹ lori rẹ? Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ko si ibi ti Ọlọrun ti paṣẹ pe ki obinrin ma wọ ṣokoto. Nitorina, a ko ni lati gbe ajaga ti ko gbe le awọn eniyan le wọn lori. Eyi ko le so eso ti a fẹ ki o so.
Niwọn igba ti Ọlọrun ko wa pa a ni aṣẹ ni ibikibi ninu ọrọ rẹ pe ki awọn obinrin ma wọ ṣokoto, ki lo wa fa ti a fi wa sọ di aṣẹ fun awọn obinrin wa ninu ọpọ ijọ wa? Aṣitunmọ bibeli ni o fa! Ṣe o ri, abala bibeli kan wa nitootọ ti o sọ nkan ti o fẹ jọ mọ pe Ọlọrun pa a ni aṣẹ fun awọn obinrin lati ma wọ ṣokoto. Amọ ọtọ patapata ni nkan ti Ọlọrun n ṣọ nibẹ. Iwọ naa wo ẹṣẹ bibeli naa:
“Obinrin ko gbọdọ wọ aṣọ ọkunrin, tabi ki ọkunrin wọ aṣọ obinrin, nitori OLUWA Ọlọrun rẹ koriira ẹnikẹni ti o ṣe eyi.” (Ditarónómì 22:5)
Kini aṣẹ ti a ri wipe Ọlọrun pa ninu ẹṣẹ bibeli yi? Ki obinrin ma ṣe wọ ṣokoto? Rara o! Aṣẹ ti O pa ni pe obinrin ko gbọdọ wọ aṣọ ọkunrin, bẹẹ si ni ki ọkunrin ki o ma ṣe wọ aṣọ obinrin. Nitorina, obinrin nikan kọ ni ọrọ yi kan – o kan ọkunrin naa.
Ibere ti o wa yẹ ki a bere ni pe, “Bawo ni a ṣe n mọ iyatọ laarin aṣọ obinrin ati aṣọ ọkunrin?” Tabi ki a bere pe, “Tani o n fi iyatọ si aarin aṣọ obinrin ati aṣọ ọkunrin?” Ti a ko ba ni pa irọ tan ara wa jẹ, a ri wipe awa eniyan naa ni a n fi iyatọ si aarin aṣọ obinrin ati aṣọ ọkunrin, ko ki i ṣe Ọlọrun. Idi si niyi ti o fi jẹ wipe kaakiri agbaye, ni orile-ede kọọkan ati laarin awọn ẹya kọọkan ni aṣa imura ọtọọtọ ti wa.
Laarin awọn Yoruba, fun apẹẹrẹ, awọn ọkunrin a ma wọ buba ati sọọrọ, iyẹn ṣokoto, pẹlu fila. Awọn obinrin naa a si ma wọ buba, ro iro ati lo gele. Ti a ko ba wa fi ọpọlọ gbe aṣẹ ti Ọlọrun pa ninu ẹṣẹ bibeli yi, o ṣeeṣe ki a bẹrẹ si ni sọ pe awọn obinrin Yoruba ti o n wọ buba n dẹṣẹ si Ọlọrun tabi pe awọn ọkunrin Yoruba ti o n wọ buba n dẹṣẹ si Ọlọrun, pẹlu idi wipe wọn n wọ aṣọ ara wọn. Amọ awọn Yoruba mọ daju ṣaka pe iyatọ nla wa larin buba ọkunrin ati buba obinrin. Iyatọ yi si wa ni arin riran awọn aṣọ wọnyi. Nitorina, niwọn igba ti obinrin ba ti wọ buba obinrin, ti ọkunrin naa si wọ buba ọkunrin, wọn ko tapa si aṣẹ ti Ọlọrun pa nibiyi.
Bẹ ẹ gẹgẹ naa ni o si ṣe ri niti ọrọ ṣokoto wiwọ. Laarin awọn ẹya ati ede ti ṣokoto wiwọ laarin awọn obinrin ti ṣẹ wa, iyatọ gedege wa laarin ṣokoto obinrin ati ṣokoto ọkunrin. Bi a ba si tun bọ si ọja loni naa pẹlu, a o ri daju ṣaka pe riran ṣokoto ọkunrin yatọ si riran ṣokoto obinrin. Nitorina, ti ọkunrin ba wọ ṣokoto obinrin, kiakia ni awọn eniyan yoo mọ pe o ti ṣi aṣọ wọ. Bẹẹ si ni, ti obinrin naa ba wọ aṣọ ọkunrin, kiakia ni awọn eniyan yoo mọ pe o ti ṣi aṣọ wọ. Bakanna ni ọrọ si ṣe ri ni ibi gbogbo.
Nitorina, ariyanjiyan ko tilẹ yẹ ki o ma waye rara lori ọrọ obinrin wọ ṣokoto tabi ko wọ ṣokoto. Idi si ni pe ọrọ lori aṣa ni wiwọ ṣokoto da le lori; ko ni nkankan ṣe pẹlu aṣẹ Ọlọrun ti o sọ pe ki obinrin ma wọ aṣọ ọkunrin ati ki ọkunrin naa ma wọ aṣọ obinrin. A tilẹ ri awọn aṣa ti awọn ọkunrin wọn ti n ro iro tabi wọ yẹri bi awọn obinrin wọn ti ṣe n ṣe. Eyi ko si ru wọn loju nitoripe aṣa wọn ni. Ti ko ba wa wu ọ, gẹgẹ bi obinrin, lati wọ ṣokoto, ko buru rara. Amọ ma ṣe idajọ obinrin miran ti o ba fẹran lati ma a wọ ọ.
Yatọ si iyẹn, boya obinrin wọ ṣokoto tabi ko wọ ṣokoto, nkan ti o ṣe pataki julọ ni ki imura rẹ jẹ iwọntunwọnsi, eyi ti yoo fi ogo fun Ọlọrun ati ti ko ni jẹ ki awọn eniyan sọrọ odi si Kirisiti. Pe obinrin ko wọ ṣokoto ko tunmọ si pe o n mura ni ọna ti o tọna, ti o si fogo fun Jesu. Ọpọ awọn obinrin wa loni ni o jẹ wipe iwọkuwọ ni wọn n wọ. Awọn miran tilẹ tun wọ awọn iwọkuwọ yi wa sinu ipade ijọ Ọlọrun. Eyi ko si bojumu rara. Nitorina, a ni lati tẹlẹ nkan ti Pọọlu sọ fun wa lori ọrọ yi, ti o ka bayi:
“Bẹẹ gẹgẹ ni ki awọn obinrin fi aṣọ iwọntunwọnsi ṣe ara wọn lọsọọ, ni iwọntunwọnsi ati pẹlu iwa airekọja, ki i ṣe pẹlu irun-didi, tabi wura, tabi peali, tabi aṣọ olowo iyebiye, Bi ko ṣe pẹlu iṣẹ rere, eyi ti o yẹ fun awọn obirnin to jẹwọ pe wọn sin Ọlọrun.” (1Tímótíù 2:9-10)
Ibere keji ti o yẹ ki a tun bere lori ọrọ yi ni pe, “Awọn wo ni a fun ni ofin yi?” Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, awọn ọmọ Isiraẹli ni a fun ni ofin yi. Eyi jasi pe a le sọ wipe ọrọ yi ko kan awọn ti ko ki i ṣe ọmọ Isiraẹli tabi awọn ọmọ Isiraẹli ti o ti da Kirisitiẹni. Pọọlu, ninu lẹta rẹ si awọn ara Kolose sọ ọrọ pupọ lori iha ti awọn Kirisitiẹni yẹ ki wọn kọ si awọn ofin Mose ati awọn ofin atọwọdọwọ miran ti o ni i ṣe pẹlu nkan ti a jẹ, mu, wọ tabi lo. Diẹ lara nkan ti o sọ ni eyi:
“Bi ẹyin ba ti ku pẹlu Kirisiti kuro ninu ipilẹsẹ aye, ee ha ti ṣe ti ẹyin n tẹriba fun ofin bi ẹni pe ẹyin wa ninu aye, Ma ṣe diimu, ma ṣe tọ ọ wo, ma ṣe fọwọbaa, Gbogbo eyi ti yoo ti ipa lilo run, gẹgẹ bi ofin ati ẹkọ eniyan? Awọn nnkan ti o ni afarawe ọgbọn nitootọ, ni adabọwọ iṣin, ati irẹlẹ, ati ipọn-ara-loju, ṣugbọn ti ko ni ere kan ninu fun ifẹkufẹ ara.” (Kólósè 2:20-22)
Ti a ba wa fi oju nkan ti Pọọlu sọ yi ati oju awọn nkan miran ti a sọ fun wa nipa iha ti o yẹ ki a kọ si ofin Mose wo ọrọ yi, iyẹn gẹgẹ bi Kirisitiẹni, a o ri wipe a ko ni lati kọbiara si ofin pe ki obinrin ma wọ asọ ọkunrin ati ki ọkunrin ma wọ aṣọ obinrin (Gàlátíà 5:1-4). Amọ ṣa o, a tun mọ wipe awọn aṣẹ Ọlọrun kan wa ti o la kalẹ ki O to fun awọn ọmọ Isiraẹli ni ofin nipasẹ Mose. A si gbọdọ ma pa irufẹ awọn aṣẹ yi mọ, yala a fun wa ni ofin Mose tabi a ko fun wa.
Fun apẹẹrẹ, a mọ lati inu bibeli wipe Ọlọrun ko fi igba kankan fọwọ si ibọriṣa, agbere, ipaniyan, ole jija ati iṣẹ oṣo. Nitori awọn nkan wọnyi ni o si ṣe pa aye igba Noa ati ilu Sodomu run. Nitorina, boya a fun wa ni ofin Mose tabi a ko fun wa, a gbọdọ yago fun awọn nkan wọnyi, nitori wọn lodi si ifẹ Ọlọrun.
Ṣe ki ọkunrin ma wọ aṣọ obinrin ati ki obinrin ma wọ asọ ọkunrin wa wa lara irufẹ awọn nkan ti Ọlọrun ti n fi ibinu rẹ han si ki O to fun awọn ọmọ Isiraẹli ni ofin nipasẹ Mose tabi ko si lara wọn? Ọna lati mọ ni ti a ba mọ idi ti Ọlọrun fi pa a lasẹ pe ki obinrin ma wọ aṣọ ọkunrin ati pe ki ọkunrin ma wọ aṣọ obinrin? Ki wa ni idi ti Ọlọrun fi pa a ni aṣẹ pe ki obinrin ma ṣe wọ aṣọ ọkunrin, ki ọkunrin naa ma si wọ aṣọ obinrin? Idi ni pe Ọlọrun fẹ ki a ma fi igba gbogbo fi iyatọ han laarin obinrin ati ọkunrin ni awujọ wa.
Eyi jasi pe, ti a ba ri obinrin, o yẹ ki a le sọ lẹsẹkẹsẹ lalai wo fínífíní pe obinrin ni. Ti a ba si ri ọkunrin pẹlu, o yẹ ki a le sọ lẹsẹkẹsẹ pe ọkunrin ni laiṣe wipe a wo fínífíní. Eyi n jẹ ki o ye wa pe Ọlọrun ko fẹ ki a ṣe ohunkohun lati pa iṣẹda wa da tabi tun ara wa da ṣi obinrin tabi ṣi ọkunrin. Alabajọ ti O fi sọ wipe Oun korira awọn obinrin ti o n wọ aṣọ ọkunrin ati awọn ọkunrin ti o n wọ aṣọ obinrin. Ti a ba tilẹ wo ọrọ ti a tunmọ si aṣọ ninu ẹṣẹ bibeli yi lati inu ede Heberu, o kọja aṣọ wiwọ nikan; o tun ni i ṣe pẹlu ohunkohun ti a ṣe fun lilo ọkunrin tabi lilo obinrin.
Nitorina, ọrọ lori ki obinrin ma mura tabi ṣe bi ọkunrin tabi ki ọkunrin ma mura tabi ṣe bi obinrin ni a n sọ nibiyi. Ki si ni yoo fa ti obinrin ti yoo fi ma mura bi ọkunrin tabi ṣe bi ọkunrin? Ati pe kini yoo fa ti ọkunrin yoo fi ma mura tabi ṣe bi obinrin, lalai ṣe wipe o n ṣe ere itage tabi sinimá? Igbiyanju lati pa iṣẹda wọn da ni o ma n fa a. Iyẹn tunmọ si pe bi Ọlọrun ṣe da awọn wọnyi ko tẹ wọn lọrun. Ete rẹ fun aye wọn ti o fi da wọn ni ọkunrin tabi ni obinrin ko tẹ wọn lọrun. Wọn si ti wa gbagbe pe aye yi nikan ni ọrọ pe a jẹ ọkunrin tabi jẹ obinrin mọ. Lẹyin aye yi, ko ni si iyatọ laarin ọkunrin ati obinrin. (Wo: Maaku 12:18-25)
Nitorina, ti Ọlọrun ba da eniyan ni ọkunrin, O ni idi. Ti O ba si da eniyan ni obinrin, O ni idi. O ni ete fun ẹnikọọkan ti O da ni ọna ti O gba da a. Lati wa gbiyanju lati tun ara wa da si ọkunrin tabi si obinrin ni lati pa ete rẹ lori aye wa run. Ara awọn nkan ti o wọpọ ni Sodomu ati Gomora niyi ti O fi pa wọn run. O si tun wa ṣeni laanu pe awọn nkan wọnyi ti n wọpọ lawujọ wa naa loni. A tilẹ ti n ri awọn ijọ Ọlọrun ti o n fọwọ si igbeyawo laarin ọkunrin ati ọkunrin ati igbeyawo laarin obinrin ati obinrin. Eyi si n fi han wa pe opin aye yi ti sunmọ etile ju bi ọpọ wa ti ṣe n ro lọ. (Wo: Jẹnẹsisi 19)
LÁKÒÓTÁN
Kedere ni a wa ri bayi wipe aṣẹ ti Ọlọrun pa lori aṣọ wiwọ laarin ọkunrin ati obinrin ko ba kiki awọn ti a fun ni ofin Mose wi; gbogbo eniyan patapata ni o ba wi. Pataki rẹ kan ni wipe ki a ma ṣi i tunmọ. Aṣitunmọ rẹ si ni ki a sọ wipe ki obinrin ma wọ ṣokoto. Ọrọ yi ko ni nkankan ṣe pẹlu obinrin wọ ṣokoto tabi ko wọ ṣokoto; o ni i ṣe pẹlu imura ti o lodi si iṣẹda obinrin ati iṣẹda ọkunrin.
ÌBÉÈRÈ
– Njẹ ẹkọ yi ran imọ rẹ lọwọ lori iha ti o yẹ ki a kọ si ọrọ lori ki obinrin wọ ṣokoto tabi ki o ma wọ ọ?
Lati ọwọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2023 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07025105978)
ÀKỌ́RÍ: Ọ̀RỌ̀ LÓRÍ ÌBÒRÍ | ÀYỌKÀ: 1KỌRINTI 11:1-16 | ỌJỌ́RÚ 15, BELU 2023
ÀKỌ́SÓRÍ: ”Ṣugbọn ti ẹnikẹni ba fẹ lati jiyan nipa rẹ, awa ko ni iru asa bẹẹ; tabi awọn ijọ Ọlọrun.” (1Kọrinti 11:1-16)
Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ
Lara awọn nkan ti o ma n fa ariyanjiyan laarin awọn ọmọ Ọlọrun ni ọrọ lori boya o pọndandan fun obinrin onigbagbọ lati bo ori rẹ ti o ba wa ni ile ijọsin awọn ọmọ Ọlọrun tabi ko pọndandan. A si wa ri ọpọ ijọ Ọlọrun ti wọn n sọ wipe dandan fun gbogbo awọn obinrin wọn lati bo ori wọn ti wọn ba ti wa ni ibi ijọsin. Awọn miran tilẹ gbe debi wipe yala awọn obinrin wọn wa ni ibi ijọsin tabi wọn ko si ni ibẹ, dandan ni fun wọn lati lo ibori. Wọn si ri eyi gẹgẹ bi aṣẹ Ọlọrun fun wọn.
Bi a ti ṣe wa ri awọn ti o pọn ni dandan fun awọn obinrin ijọ wọn lati ma lo ibori, paapaa-julọ ti wọn ba wa ni ipade awọn ọmọ Ọlọrun tabi ibi adura, naa ni a si tun ri ọpọ ijọ loni ti wọn n sọ wipe ko pọndandan fun obinrin kankan lati bo ori rẹ ti o ba wa ni ipade awọn ọmọ Ọlọrun. Awọn wọnyi ri lilo ibori gẹgẹ bi aṣa lasan ti ko ni nkankan ṣe pẹlu ọkan ti eniyan fi n sin Ọlọrun. Ta wa gan ni ki a gbagbọ laarin awọn wọnyi? Tani gan ninu wọn ni o n tẹle ifẹ Ọlọrun lori ọrọ yi? Ṣe awọn ti o pọn ni dandan fun awọn obinrin wọn lati ma lo ibori ninu ipade wọn ni tabi awọn ti o pọn ni dandan fun awọn obinrin wọn lati ma lo ibori nibikibi ti wọn ba lọ tabi awọn ti wọn ni ko jamọ nkankan boya obinrin lo ibori ninu ipade awọn ọmọ Ọlọrun tabi ko lo o?
Eyi ni a fẹ gbe yẹwo ninu ẹkọ bibeli yi. A fẹ mọ nkan ti bibeli sọ gan an lori ọrọ yi, ki a ba le mọ iha ti o tọ fun wa lati kọ si. O si wa ṣe pataki ki gbogbo ọmọ Ọlọrun mọ nkan ti bibeli sọ ni pato lori ọrọ naa. Nitori a ri wipe ọpọ laarin awọn obinrin wa ti ko ki lo ibori ninu awọn ipade ijọ wọn tabi ni asiko adura ni ko mọ ifẹ tabi aṣẹ Ọlọrun lori ọrọ yi. Bẹẹ si ni pẹlu, ọpọ lara awọn obinrin wa ninu ijọ ti o n lo ibori ni ko mọn nkan ti Ọlọrun sọ ni pato nipa rẹ. Eyi lo fa ti awọn miran fi ma n ja ohun yowu ti wọn ba ri mọ ori lasiko adura tabi ti wọn ba wọ ibi ipade awọn ọmọ Ọlọrun. Mo tilẹ ti ri awọn ti wọn fi iwe ọwọ wọn bori ni asiko adura nitoripe wọn gba pe ko tọna lati ṣi ori wọn silẹ ti adura ba n lọ lọwọ. Ṣugbọn ṣe ninu bibeli naa ni wọn ti kọ eyi? Ko jẹ jẹ bẹẹ!
Nikukuru, pataki ẹkọ yi ni lati wo nkan ti bibeli sọ lori ọrọ ibori fun awọn obinrin ninu ipade awọn ọmọ Ọlọrun ati lati ni asiko adura. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun fi oye kun ọkan wa bi a ti n farabalẹ lati gbe ọrọ naa wo nipasẹ agbara Ẹmi Mimọ rẹ. Amin.
Ọ̀RỌ̀ LÓRÍ ÌBÒRÍ
Wayi o, ki gan an ni bibeli sọ lori ọrọ lilo ibori ninu ijọ? Ọna kanṣoṣo ni a ti ri eyi ninu bibeli, iyẹn ninu lẹta Pọọlu si awọn ara Kọrinti. Nitorina, ti oye nkan ti a sọ lori rẹ yoo ba ye wa daradara, a gbọdọ ṣe agbeyẹwo ohun gbogbo ti Pọọlu kọ silẹ lori rẹ, ki a ma kan mu abala ti o ba wu wa tabi ti o ba ero ọkan wa mu lori ọrọ naa. Aijẹbẹ, o di dandan ki a gbe nkan ti o n sọ gbagi. Ki lo wa sọ o? O sọ wipe:
“Njẹ ara, mo yin yin nitori ti ẹyin n ranti mi ninu oun gbogbo, ti ẹyin si n ṣe gẹgẹ bi ẹkọ wọn-ọn-ni, ani gẹgẹ bi mo ti fi wọn le yin lọwọ. Ṣugbọn mo fẹ ki ẹyin ki o mọ pe, Kirisiti ni olori olukuluku ọkunrin; olori obinrin si ni ọkọ rẹ; ati olori Kirisiti si ni Ọlọrun. Olukuluku ọkunrin ti n gbadura tabi ti n sọtẹlẹ ti o si bo ori rẹ, o se alaibọwọ fun ori rẹ, eyi ti n ṣe Kirisiti. Ṣugbọn olukuluku obinrin ti n gbadura tabi ti n sọtẹlẹ ni aibo ori rẹ, o ṣe alaibọwọ fun ori rẹ, eyi ti n ṣe ọkọ rẹ: nitori ọkan naa ni pẹlu ẹni ti o fari. Nitori bi obinrin ko ba bo ori, ẹ jẹ ki o ge irun rẹ pẹlu: ṣugbọn bi o ba ṣe pe ohun itiju ni fun obinrin lati ge irun tabi lati fari rẹ, jẹ ki o bo ori. Nitori nitootọ ko yẹ ki ọkunrin ki o bo ori rẹ, niwọnbi oun ti jẹ aworan ati ogo Ọlọrun: ṣugbọn obinrin ni i ṣe ogo ọkunrin. Nitori ọkunrin ko ti ara obinrin wa; ṣugbọn obinrin ni o ti ara ọkunrin wa. Bẹẹ ni a ko da ọkunrin nitori obinrin; ṣugbọn a da obinrin nitori ọkunrin. Nitori eyi ni o fi yẹ fun obinrin lati ni ami aṣẹ ni ori rẹ, nitori awọn angẹli. Ṣugbọn ọkunrin ko le ṣe laisi obinrin, bẹẹ ni obinrin ko le ṣe laisi ọkunrin ninu Oluwa. Nitori gẹgẹ bi obinrin ti ti ara ọkunrin wa, bẹẹ ni ọkunrin tipasẹ obinrin wa pẹlu: ṣugbọn lati ọdọ Ọlọrun ni ohun gbogbo ti wa. Ẹ gba a ro laarin ẹyin tikarayin: o ha tọ ki obinrin ki o maa gbadura si Ọlọrun laibori bi? Ẹyin ko ha mọ nipa ẹda pe, bi ọkunrin ba ni irun gigun, abuku ni fun un? Ṣugbọn bi obinrinn ba ni irun gigun, ogo ni o jẹ fun un, nitori ti a fi iru rẹ fun un gẹgẹ bi ibori. Ṣugbọn bi ẹnikẹni ba fẹ lati jiyan nipa rẹ, awa ko ni iru aṣa bẹẹ, tabi awọn ijọ Ọlọrun.” (1Kọrinti 11:1-16)
Kini nkan akọkọ ti a ri ninu akọsilẹ Pọọlu yi? Ohun naa ni pe ko ki i ṣe kiki awọn obinrin onigbagbọ ni ọrọ lori ibori ba wi; o ba awọn ọkunrin onigbagbọ naa wi. Idi si nipe, fun apẹrẹ, aṣa awọn ọkunrin Juu ni lati ma bo ori wọn pẹlu aṣọ tabi fila ti wọn ba n gbadura. A tilẹ tun rigbọ lati ẹnu awọn onkọtan pe aṣa awọn ọkunrin Roomu ni pẹlu lati ma bo ori wọn ti wọn ba n jọsin. Ṣe eyi wa wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun awọn ọkunrin Kirisitiẹni bi? Rara!
Ki a to wa tẹsiwaju, a kọkọ nilo lati kiyesi asiko tabi igba ti ọrọ lilo ibori ni iwulo. Bi Pọọlu ti ṣe jẹ ki o ye wa, ọrọ ibori lilo ni i ṣe pẹlu asiko ti a ba n gbadura, sọtẹlẹ tabi waasu. Eyi jasi pe, bi a tilẹ wa ninu ipade awọn ọmọ Ọlọrun, niwọn igba ti a ko ba ma gbadura apapọ tabi pe a fẹ sọtẹlẹ tabi waasu, ofin lilo ibori ko mu wa.
Siwaju si, bi o tilẹ jẹ wipe Juu ni Pọọlu, ti o si mọ wipe awọn ọkunrin Juu ma n bo ori wọn ti wọn ba n gbadura, o jẹ ki o ye wa ninu abala lẹta rẹ yi pe o lodi si ifẹ Ọlọrun fun ẹni ti o gbagbọ ninu Jesu lati ma gbadura, sọtẹlẹ tabi waasu pẹlu ori bibo, ti o ba jẹ ọkunrin. Ki ni idi? Nkan meji ni Pọọlu so pọ lati fi idi ọrọ yi mulẹ fun wa. Akọkọ ni pe Kirisiti ni ori ọkunrin onigbagbọ kọọkan. Ekeji ni wipe a da ọkunrin ni ibẹrẹ-pẹpẹ gẹgẹ bi aworan ati ogo Ọlọrun. Nitorina, ọkunrin ti o ba n bo ori rẹ ni asiko ti o n ba Ọlọrun sọrọ tabi ti o n ṣiṣẹ gẹgẹ bi iriju Ọlọrun n bo ogo ati ẹwa Ọlọrun mọlẹ. Eyi jasi pe o n ṣe aibọwọ fun Kirisiti, ẹni ti o jẹ ori rẹ. Njẹ eyi wa tọna bi? Ko tọna rara.
Ọna wo wa ni ọrọ yi ṣe kan awọn obinrin? Pọọlu jẹ ki o ye wa. Gẹgẹ bi o ti sọ, ko tọna fun obinrin Kirisitiẹni lati ṣi ori rẹ silẹ ti o ba n gbadura, sọtẹlẹ tabi waasu. Kini idi? Nkan mẹta ni apọsiteli yi tun so pọ lati fi idi ọrọ yi mulẹ. Akọkọ, ọkunrin ni ori gbogbo obinrin ti o ba ti ni ọkọ. Ekeji, obinrin jẹ ogo ọkunrin, iyẹn ọkọ rẹ. Idi si ni pe lati ipasẹ ọkunrin ni a ti ṣe da obinrin; a ko da ọkunrin lati ipasẹ obinrin. Yatọ si iyẹn, a da obinrin fun ọkunrin ni; a ko da ọkunrin fun obinrin. Lotitọ, ọkunrin ko le da wa laisi obinrin, gẹgẹ bi obinrin ko ṣe le da wa lalai si ọkunrin. Amọ ṣa o, ni ibẹrẹ-pẹpẹ nitori ọkunrin ni a ṣe da obinrin. Idi si niyi ti obinrin ṣe gbọdọ ri ọkọ rẹ gẹgẹ bi ori rẹ, ki o si tẹriba fun. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 2:18-25)
Wayi o, nitori nkan meji ti Pọọlu sọ silẹ yi, obinrin ti ko ba lo ibori ni asiko ti o ba n gbadura, sọtẹlẹ tabi waasu n ṣe aibọwọ fun ori rẹ, iyẹn ọkọ rẹ. O wa yẹ ki a kiyesi ẹni ti obinrin ti ko lo ibori lọna yi n ṣe aibọwọ fun. Tani ẹni naa? Ṣe Ọlọrun ni o n ṣe aibọwọ fun? Rara o! Ọkọ rẹ ni o n ṣe aibọwọ fun. Nitorina, ailo ibori obinrin ni asiko ti o n gbadura, sọtẹlẹ tabi waasu ko pa ibaṣepọ rẹ pẹlu Ọlọrun lara – ibaṣepọ rẹ pẹlu ọkọ rẹ ni n pa lara.
Lọna wo wa ni irufẹ obinrin yi ṣe n ṣe aibọwọ fun ọkọ rẹ? O n ṣe aibọwọ fun ọkọ rẹ nitoripe aṣa laarin awọn Giriki, eyi ti awọn ara Kọrinti n ṣe ara wọn, ni ki awọn obinrin ti o ti wa nile ọkọ bo ori wọn ni awujọ awọn eniyan. Obinrin ti ko ba lo ibori ni awujọ awọn eniyan n sọ wipe ko si ọkọ tabi ade ni ori oun niyẹn. O wa jẹ wipe irufẹ obinrin yi si jẹ omidan tabi aṣẹwo.
Nitorina, laarin Giriki ni asiko ti a n sọ yi, o ṣe pataki ki obinrin onigbagbọ lo ibori ni awujọ awọn ọmọ Ọlọrun, paapaa julọ ni igbakugba ti o ba n gbadura, sọtẹlẹ tabi waasu. Eyi yoo jẹ ki awọn eniyan mọ wipe o wa labẹ itẹriba fun ọkọ rẹ. Yatọ si iyẹn, yoo fi han pe o n daabo bo ogo ọkọ rẹ – ko fi aye silẹ fun ẹnikẹni lati ri gẹgẹ bi aṣewo ti wọn le kọ ẹnu si lọna ti o ba wu wọn. Aijẹbẹ, yoo mu ẹgan ba iyinrere ati ọrọ otitọ Jesu Kirisiti.
Bi Pọọlu tun ṣe wa jẹ ki o ye wa, awọn eniyan ti o n wo wa nikan kọ ni ọrọ yi kan; o kan awọn angẹli Ọlọrun pẹlu. Awọn angẹli Ọlọrun, bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ma n wa pẹlu gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun, pẹlupẹlu ninu awọn ipade wa. O wa yẹ ki wọn ri ami aṣẹ, iyẹn ami itẹriba fun ọkọ, lori obinrin kọọkan ti o wa nile ọkọ ninu ipade awọn Giriki wọnyi. Aijẹbẹ, wọn yoo ka obinrin naa si alainitẹriba. Ọna ti eyi yoo wa gba pa iṣẹ iṣin rẹ lara ni a ko le sọ. Eyi si ni idi kẹta ti Pọọlu fi lọlẹ fun pataki ki obinrin ma lo ibori ti o ba n gbadura, sọtẹlẹ tabi waasu. (Wo: Hébérù 12:22)
Kedere ni a wa ri bayi pe lilo ibori laarin awọn obinrin onigbagbọ ni ipade awọn ọmọ Ọlọrun tabi ni asiko adura gbigba ni i ṣe pẹlu nkan meji pataki. Akọkọ, o ni ṣe pẹlu ipo obinrin naa ni awujọ, iyẹn ni wipe ṣe o ti lọkọ tabi ko ni ọkọ. Eyi jasi pe ofin ibori ko mu obinrin ti ko si ni ile ọkọ tabi ti ko ti lọkọ. Nitorina, ko tọna fun wa lati kan nipa fun irufẹ obinrin naa lati lo ibori ni awọn ipade wa tabi ni asiko ti o ba n waasu, sọtẹlẹ tabi gbadura. Yatọ si eyi, niwọn igba ti o ba jẹ wipe ninu ile ọkọ rẹ ni obinrin yi wa ati laarin ẹbi rẹ, nibi ti ko ti ni lati lo ibori rara, ko ni nilo lati lo ibori naa ti o ba tilẹ ni lati gbadura, waasu tabi sọtẹlẹ.
Ekeji, o ni i ṣe pẹlu aṣa ibi ti o ba wa. Awọn ibi ti lilo ibori ba ti jẹ aṣa ti o n fi adelebọ tabi awọn obirin ti o wulo lawujọ han ni o ti ṣe pataki ki obinrin lo ibori ni ipade awọn ọmọ Ọlọrun. Ibi ti ko ba ti jẹ aṣa ti o n fi obinrin ti o ti lọkọ tabi omidan ti ko ki i ṣe aṣewo han, obinrin onigbagbọ ko nilo lati lo ibori ni ipade awọn ọmọ Ọlọrun nibẹ, boya o n gbadura, sọtẹlẹ tabi waasu. Nkan ti o ba jẹ aṣa ti yoo fi han nibẹ gẹgẹ bi ẹni ti o ti lọkọ, ti o si tẹriba fun ọkọ rẹ, tabi ẹni ti o wulo lawujọ ni o gbọdọ lo nibẹ.
Fun apẹẹrẹ, o ti di aṣa ni ọpọ ibi loni pe ki awọn obinrin ti o ba ni ọkọ lo oruka igbeyawo si ika ọwọ wọn ti a n pe ni orukayẹmi. Nitorina, nibi ti aṣa yi ba ti mulẹ, o ṣe pataki ki obinrin onigbagbọ ti o ba ti ni ọkọ ri daju pe oun lo orukọ igbeyawo. Eyi yoo jẹ ami itẹriba fun ọkọ rẹ loju awọn eniyan ati loju awọn Angẹli.
Amọ, a ko wa gbọdọ foju fo o pe o ṣeeṣe ki obinrin lo ibori, lo oruka igbeyawo tabi ṣe ohun miran ti yoo fihan gẹgẹ bi ẹni ti o wa labẹ aṣẹ ọkọ rẹ ni ita, ki o si ma bọwọ tabi tẹriba fun ọkọ rẹ rara. Ti ẹni ti o ba wa n ṣe eleyi ba ri awọn eniyan tan jẹ, ko le ri Ọlọrun tabi awọn angẹli rẹ tan jẹ. Nitorina, nṣe ni ọrun yoo ka si ẹni ti o n tabuku ọkọ rẹ, bi o tilẹ jẹ wipe o n lo nkan ti o n ṣami pe o ni itẹriba fun ọkọ.
Lati wa pari ọrọ rẹ, Pọọlu tun wa fi nkankan kun awọn ilana ti o ti la kalẹ ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun lori lilo ibori. Eyi si ni i ṣe pẹlu ki a ṣe iyatọ ti o han kedere laarin awọn ọkunrin ati obinrin ninu ijọ Ọlọrun. Bi a ti ṣe ri awọn ọkunrin ti o n ṣe bi obinrin ati awọn obinrin ti wọn n ṣe bi ọkunrin loni naa ni a ṣe ri wọn ni asiko ti Pọọlu kọ iwe yi si awọn ara Kọrinti. A si tun wa ri awọn ijọ Ọlọrun ti o n fi aye gba igbakugba yi laarin wọn. Eyi ko wa gbọdọ ribẹ ni Pọọlu n jẹ ki o ye wa.
Bi o ti ṣe sọ siwaju, Ọlọrun ti fi iyatọ si arin awọn ọkunrin ati obinrin nipa iṣẹda wọn lati ibẹrẹ-pẹpẹ. Lara awọn iyatọ yi si ni irun ori wa wa. Lọna wo? A da awọn obinrin ki irun ori wọn pọ, ki o si tun gun. Idi niyi ti o ṣe ma n dabi nkan abuku fun obinrin lati ma ni irun lori pupọ. Pọọlu tilẹ jẹ ki o ye wa pe Ọlọrun mọ-ọn-mọ fun awọn obinrin ni irun pipọ ni, ki o ba le jẹ ibori fun wọn. Nitorina, yatọ si ibori ti o ni i ṣe pẹlu ami igbeyawo, ibori ti wa lori obinrin naa.
Ṣugbọn a ko da awọn ọkunrin ki irun ori wọn gun. Nkan abuku ni a tilẹ ka a si ni ọpọ ibi fun ọkunrin lati ma gbe irun gigun kaakiri. A wa gbọdọ ri daju pe awọn iyatọ yi farahan kedere ninu gbogbo awọn ijọ wa, paapaa-julọ ni awọn ipade wa. Eyi jasi pe a ko gbọdọ fi aye gba imura tabi iṣesi yowu ti ko ni jẹ ki a da awọn ọkunrin ti o wa ni aarin wa mọ yatọ si awọn obinrin ti o wa ni aarin wa. A ko si tun gbọdọ pa awọn ami ti yoo jẹ ki a mọ iyatọ laarin awọn ti o ti lọkọ tabi ni aya laarin wa rẹ. Aijẹbẹ, ko ni si ibọwọ ati itẹriba ti o peye ninu awọn ijọ wa. Eyi yoo si jẹ ki orukọ Jesu ti ipasẹ wa di isọrọ-odi si.
Ọ̀rỌ̀ ÌPARÍ
Lilo ibori ati ailo ibori ninu ijọ ni iṣe pẹlu aṣẹ Ọlọrun, ipo igbeyawo ati aṣa ilẹ yowu ti a wa. A wa gbọdọ mọ iyatọ laarin ibi ti o ti sorọ mọ aṣẹ Ọlọrun, ipo igbeyawo tabi aṣa ilẹ wa. Aijẹbẹ, a ko ni dẹku ariyanjiyan ailojotu ti a n fi gbogbo igba ni lori ọrọ naa.
IBEERE
- Se alaye ni soki bi ẹkọ yi ti ṣe ye ọ si?
Lati ọwọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2023 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07025105978)
ỌJỌ́RÚ 01, BELU 2023
ÀKỌ́RÍ: RÁNTÍ AYA LỌ́Ọ̀TÌ
ÀYỌKÀ: LÚÙKÙ 17:26-37
ÀKỌ́SÓRÍ: ”Ẹni ti o ba n wa ati gba ẹmi rẹ la yoo sọ ọ nu; ẹnikẹni ti o ba si sọ ọ nu yoo gba a la.” (Luuku 17:33)
Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ
Ara awọn nkan ti a fi ye wa yekeyeke ninu bibeli ni wipe aye ti a wa ninu rẹ ati awọn ọrun ti a n ri yi ko ni wa titi lailai. Ki ni idi? Idi ni wipe idibajẹ ti wọ inu wọn lati ipasẹ ẹṣẹ eniyan. Ẹṣẹ eniyan fi aye silẹ fun Satani ati awọn ọmọ ogun rẹ lati fi idibajẹ ti ko ṣe fẹnusọ sori ohun gbogbo ti Ọlọrun da. Nitorina, Ọlọrun, ti ko ki fi aaye gba ohunkohun ti o ba jẹ idibajẹ tabi èérí ni lati pa aye ati ọrun run, ki O si fi idi aye ati ọrun miran ti O ti ṣeto silẹ lọlẹ. Peteru mẹnuba eyi ninu lẹta rẹ keji nigbati o sọ wipe:
“Ṣugbọn ọjọ Oluwa n bọwa bi ole ni oru; ninu eyi ti awọn ọrun yoo kọja lọ pẹlu ariwo nla, ati awọn imọlẹ oju ọrun yoo si ti inu ooru gbigbona gidigidi di yiyọ, aye yati awọn iṣẹ ti o wa ninu rẹ yoo si jona lulu. Njẹ bi gbogbo nnkan wọnyi yoo ti yọ bẹẹ, iru eniyan wo ni ẹyin iba jẹ ninu iwa mimọ gbogbo ati iwa-bi-Ọlọrun. Ki ẹ maa reti ki ẹ si maa mura giri de dide ọjọ Ọlọrun, nitori eyi ti awọn ọrun yoo gbina, ti wọn yoo di yiyọ, ti awọn imọlẹ rẹ yoo si ti inu ooru gbigbona gidigidi di yiyọ. Ṣugbọn gẹgẹ bi ileri rẹ, awa n reti awọn ọrun tuntun ati aye titun ninu eyi ti ododo n gbe.” (2Peteru 3:10-13)
Awọn wo ni Peteru n sọ nkan wọnyi fun? Awọn ti o gbagbọ ninu Jesu Kirisiti Oluwa wa ni o n sọ wọn fun. Awọn ni o ni lati ma fi gbogbo igba ranti pe aye yi ko ni lọ titi lailai ati wipe opin yoo de ba ni ọjọ kan. Bẹẹ si ni, awọn ni o ni lati ma ranti ni ọjọ gbogbo pe ohun gbogbo ko pin sinu aye yi – ayeraye ṣi n bọ wa. Niwọn igba ti ayeraye wa n bọ wa, wọn nilo lati mura de e, ki o ma ba ba wọn ni ojiji ati ni aimurasilẹ. Aijẹbẹ, oore-ọfẹ igbala ti wọn ri gba ko ni jamọ nkankan mọ nikẹyinkẹyin.
RÁNTÍ AYA LỌ́Ọ̀TÌ
Ki awa ti a gbagbọ ninu Jesu Oluwa wa ma ba wa sọ anfaani oore-ọfẹ igbala wa nu, O kilọ fun wa gidigidi nipa lilo awọn iṣẹlẹ kan ti o ti ṣẹlẹ ṣẹyin lati ma fi gbogbo igba wa ni imurasilẹ ati lati ma boju wẹyin. Ọkan pataki lara awọn iṣẹlẹ ti O si lo lati kọ wa ni pataki ki a mura silẹ de ọjọ ti aye yi ati ohun gbogbo ti o n lọ ninu rẹ yoo bẹrẹ si ni wa si opin ni iṣẹlẹ idajọ Sodomu ati Gomora.
Bawo ni ti Sodomu ati ti Gomora ti jẹ ri? Sodomu ati Gomora jẹ ilu pataki meji ni igba aye Aburahamu ati Lọọti, ọmọ arakunrin rẹ. Sodomu gan tilẹ wa ni Lọọti fi ṣe ibugbe nigba ti oun ati Aburahamu nilo lati pinya, ki aaye ba le gba awọn mejeji ati ọrọ̀ wọn. Amọ awọn ilu mejeji yi, Sodomu ati Gomora, ko ni ẹri rere niwaju awọn eniyan ati niwaju Ọlọrun ni asiko yi. Iwọ naa wo nkan ti a sọ nipa wọn ninu bibeli: “Ṣugbọn awọn ọkunrin Sodomu jẹ eniyan buburu, wọn si n dẹṣẹ gidigidi ni iwaju Oluwa.” (Jẹ́nẹ́sísì 13:13) Ki ni a sọ nipa awọn ara Sodomu ninu ẹṣẹ bibeli yi? A sọ wipe wọn n dẹṣẹ gidigidi niwaju Oluwa.
Ṣe awọn ara Sodomu ati Gomora nikan ni o wa n dẹṣẹ niwaju Ọlọrun ni asiko yi ni? Rara o! Kaakiri agbaye ni awọn eniyan ti n dẹṣẹ si Ọlọrun ni asiko naa. Amọ, ko ki i ṣe ibi gbogbo naa ni ẹṣẹ ti gbilẹ bi o ti ṣe gbilẹ ni awọn ilu wọnyi. Fun apẹẹrẹ, nigba ti Ọlọrun n ba Aburahamu sọrọ nipa ilẹ Kenani ti O ti ṣeleri lati fun oun ati arọmọdọmọ rẹ, O sọ eyi fun un, “Ni iran kẹrin awọn iran rẹ yoo pada wa si ibi. Nitori ẹṣẹ awọn ara Amori ko i ti i kun oṣuwọn.” (Jẹnẹsisi 15:16) Eyi jẹ ki o ye wa pe Ọlọrun ma n wo oṣuwọn ẹṣẹ awọn eniyan lati sọ asiko ti yoo ṣe idajọ wọn. A ri wipe o ṣe eleyi ni igba aye Nọa ki o to ṣe idajọ eniyan. Nitorina, ti o ba da bi ẹni pe Ọlọrun lọra lati ṣe idajọ awọn eniyan tabi lati fi opin si aye ẹṣẹ yi, ara idi ni pe O ma n wo oṣuwọn ẹṣẹ ki O to ṣe idajọ.
Ni kukuru, bi o tilẹ jẹ wipe awọn ara Sodomu nikan kọ ni o n dẹṣẹ ni asiko ti a n sọ yi, Ọlọrun kiyesi ẹṣẹ wọn nitori wipe o pọ gidigidi. Ẹṣẹ wọn pọ to bẹẹ gẹẹ ti Ọlọrun fi sọ eyi fun Aburahamu ni asiko ti O fẹ ṣe idajọ wọn: “Igbe Sodomu ati Gomora pọ pupọ ati pe ẹṣẹ wọn buru jọjọ. Emi yoo sọkalẹ sibẹ lati ṣe iwadii igbe ti o de si eti igbọ mi nipa wọn, ki emi si mọ otitọ ti o wa nibẹ.” (Jẹnẹsisi 18:20-21) Njẹ o ri bayi? Ẹṣẹ awọn ara Sodomu ati Gomora pọ debi wipe Ọlọrun nilo lati ṣebi eniyan wa si ọdọ wọn pẹlu awọn angẹli rẹ meji kan lati fi oju to nkan ti o n lọ nibẹ gan an.
Bi o tilẹ wa jẹ wipe Aburahamu ṣipẹ fun awọn ilu yi, nitori Lọọti, ọmọ arakunrin rẹ ti o n gbe aarin wọn, ẹpa ko ma boro lọrọ wọn. Iṣipẹ rẹ ko to fun igbala wọn. Idi si ni pe wọn tun gbiyanju lati ṣe awọn angẹli ti a ran bi eniyan si aarin wọn ni ijamba. Lọọti ati idile rẹ nikan ni o yatọ gedegbe laarin wọn. Oun ati idile rẹ ni o gba awọn angẹli yi ni alejo. Oun ati idile rẹ nikan ni o n gbe igbe aye ti o mọ, ti o si yatọ nibẹ. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 19:1-2)
Nitorina, Lọọti ati ile rẹ ri oore-ọfẹ igbala gba ni ọjọ ti a sọ yi. Awọn nikan ni awọn angẹli yi sọ eredi ti wọn ṣe wa si Sodomu ati Gomora fun. Awọn nikan ni wọn tun fun ni anfaani lati sare tete kilọ fun awọn ti o jẹ tiwọn ninu awọn ilu yi, ki awọn naa ba le ri igbala. O wa ṣeni laanu pe ko si ẹni ti o gbọ ti Lọọti ni ọjọ ti a n wi yi. Nṣe ni awọn ti o ba sọrọ, iyẹn awọn ọkọ afẹsọna awọn ọmọbinrin rẹ, ro wipe o n ṣe awada. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 19:12-14)
Bakan naa ni o si ṣe ri titi di asiko yi. Ti a ba n sọ fun awọn eniyan nipa bibọ Jesu ati opin aye, ọpọ ni o ma n ro wipe ahesọ ọrọ tabi awada ni. Ṣugbọn ni ọjọ ti oṣuwọn ẹṣẹ gbogbo awọn ti o wa ni orilẹ-ede aye yi ba kun, o di dandan ki idajọ Ọlọrun bẹrẹ. Ta wa ni o mọ ọjọ yi? Ko si. Ọlọrun nikan ni O mọ ọn. Bi ko ti si ẹni ti o mọ ọjọ ti Ọlọrun yoo ṣe idajọ ni asiko Nọa titi asiko fi to, ti ko si si ẹni ti o mọ ọjọ ti Ọlọrun yoo ṣe idajọ Sodomu ati Gomora titi asiko fi to naa ni ko ni si ẹni ti yoo mọ ọjọ ti Ọlọrun yoo mu aye yi ati ohun gbogbo ti o n lọ ninu rẹ wa si opin titi asiko yoo fi to. A si fi idi eyi mulẹ ṣinṣin ninu bibeli. (Wo: Mátíù 24:42; Mátíù 25:13; Máàkù 13:33; 1Tẹsalóníkà 5:1-3)
Ni kukuru, nitoripe Lọti ati ile rẹ ri oore-ọfẹ Ọlọrun gba ni ọjọ ti a n wi yi, awọn angẹli ti a ran lati pa Sodomu ati Gomora run paṣẹ fun wọn lati jade kuro ninu awọn ilu wọnyi ni kiakia. Iwọ naa wo nkan ti a sọ nipa rẹ:
“Ni afẹmọju, awọn angẹli naa rọ Lọti pe, “Ṣe were, mu aya rẹ ati awọn ọmọbinrin rẹ mejeeji ti o wa nihinin, aiṣe bẹẹ, iwọ yoo parun pẹlu ilu yii nigba ti wọn ba n jiya ẹṣẹ wọn.” Nigba ti o n jafara, awọn ọkunrin naa nawọ mu un lọwọ, wọn si nawọ mu aya rẹ naa lọwọ ati awọn ọmọbinrin rẹ mejeeji, wọn si mu wọn jade ṣeyin odi ilu, nitori OLUWA ṣaanu fun wọn. Ni kete ti wọn mu wọn jade tan, ọkan ninu awọn Angẹli naa wi fun wọn pe, “Ẹ ṣa asala fun ẹmi ti yin, ẹ ma ṣe wẹyin, ori oke ni ki ẹ sa lọ, ẹ ma ṣe duro ni pẹtẹlẹ, aiṣe bẹẹ, ẹyin yoo ṣegbe!”” (Jẹ́nẹ́sísì 19:15-17)
Ki ni nkan akọkọ ti awọn angẹli Ọlọrun yi kọkọ fi ye Lọti? Oun naa ni pe ti ko ba fi Sodomu silẹ, oun ati idile rẹ yoo parun pẹlu wọn. Ṣe ifẹ Ọlọrun ni ki wọn parun pẹlu awọn ara Sodomu ati Gomora? Rara! Amọ ti idajọ Ọlọrun ba ka wọn mọ arin awọn eniyan yi, awọn naa yoo parun pẹlu wọn. Eyi ko tunmọ si pe wọn yoo lọ si ọrun apadi o. Amọ wọn yoo fi iku aitọjọ ṣe ifajẹ.
Ẹkọ ti eyi si n kọ wa ni pe o ṣeeṣe ki olododo kopa ninu ijiya awọn ẹlẹṣẹ ti ko ba yago tabi yẹra fun wọn ni asiko idajọ Ọlọrun. Idi niyi ti a si ṣe paṣẹ fun wa ninu bibeli pe ki a ma fi aidọgba dapọ pẹlu awọn alaigbagbọ (2Kọ́ríntì 6:14-18). Aijẹbẹ, o ṣeeṣe ki a kopa ninu ijiya ẹṣẹ wọn, yatọ si pe wọn le fi idibajẹ sinu aye wa nipasẹ ibaṣepọ wa pẹlu wọn.
Nkan ekeji ti awọn angẹli yi fi ye Lọti ni pe yatọ si pe oun ati idile rẹ gbọdọ fi Sodomu silẹ, wọn nilo lati ṣebẹ ni kiakia ati pẹlu ere, ki wọn si ma boju wẹyin rara. Eyi tunmọ si pe wọn gbọdọ gbagbe nipa Sodomu patapata ati ibaṣepọ yowu ti wọn ni pẹlu rẹ. Ọkan wọn ko tun gbọdọ fa si ilu yi tabi si ohunkohun ti wọn ni ninu rẹ mọ. Idi si ni pe ṣiṣe bẹ yoo ṣe iparun fun aye wọn.
Ṣe Lọti, aya rẹ ati awọn ọmọ rẹ wa tẹle aṣẹ awọn angẹli yi bi? Bẹẹni, wọn tẹle. Amọ, wọn lọra lati tẹle. Wọn lọra debi wipe awọn angẹli yi ni lati ti wọn lọpọnpọn jade kuro ni Sodomu. Wọn ṣe eyi nitoripe Ọlọrun ti pinnu lati saanu fun wọn. Ti Ọlọrun ba lọ wo ilọra wọn ni, nṣe ni ko ba pa wọn run pẹlu awọn ara Sodomu. Amọ ko wo o. Dipo bẹẹ, o mu suuru fun wọn lati jade kuro ni Sodomu. O tilẹ paṣẹ fun awọn angẹli rẹ lati ma ṣe nkankan si awọn ilu yi titi Lọti ati idile rẹ yoo fi sa asala fun ẹmi wọn. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 19:18-25)
Eyi si n jẹ ki o ye wa pe ti Ọlọrun ba fẹ ṣaanu fun eniyan lati pa wọn mọ, O ma tun n mu suuru fun wọn. A ri ka ninu bible naa pe Ọlọrun mu suuru fun Nọa lati pari ọkọ oju omi ti oun, idile rẹ ati awọn nkan ọsin ti Ọlọrun fẹ pamọ pẹlu rẹ yoo farapamọ si nigba ti idajọ rẹ ba de sori aye (1Pétérù 3:20). A ko wa gbọdọ ṣi suuru Ọlọrun lo, ki a fi pe e ni ọdẹ. Eyi le yọri si ewu fun aye tabi ọkan wa. (Wo: Róòmù 2:4; 2Pétérù 3:9)
Bi a ti ṣe ri ninu itan Lọti, bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun ṣaanu fun oun ati ile rẹ, aya rẹ si papa ṣe aigbọran si aṣẹ awọn angẹli yi. O bojuwẹyin, o si di ọ̀wọ́n tabi ki a pe ni òpó iyọ (Jẹ́nẹ́sísì 19:26). Ki lo wa fa ti o ṣe bojuwẹyin? Ṣe aigbagbọ ninu Oluwa ni? Rara o. O gbagbọ ninu Ọlọrun, o si bẹru rẹ pẹlu. Idi niyi ti oun naa ṣe sa asala kuro ni Sodomu pẹlu ọkọ ati awọn ọmọbinrin rẹ. Ki lo wa jẹ ki o bojuwẹyin? Nkan ti o fa ilọra oun ati ọkọ rẹ naa ni o jẹ ki o boju wẹyin.
Ki lo fa ilọra wọn? A ko mẹnuba taarataara. Amọ ṣa, a jẹ ki o ye wa ninu bibeli pe ọlọrọ ni Lọti ni asiko yi (Jẹ́nẹ́sísì 13:5). Ko si wa ni anfaani lati ko ẹru ati ọrọ rẹ kuro ninu ilu yi nitoripe eyi yoo jẹ ki idajọ Ọlọrun ba ni Sodomu ati Gomora. Nitorina, ti a ba sọ wipe ọrọ̀ rẹ ti o wo bi yoo ṣe ko lọwọ ni o fa ilọra rẹ, a ko ni jayòpa. Ti a ba sọ wipe ọrọ̀ wọn, gbogbo nkan ti wọn fi ọjọ owurọ wọn ṣe, ti wọn ko ri ko jade ni Sodomu, ni o fa ti iyawo rẹ fi bojuwẹyin, a ko ni jayòpa. Ohun yowu ti o le jẹ, bi ko tilẹ jẹ ọrọ wọn, nkan naa ṣe iyebiye ni ọkan iyawo rẹ debi wipe ko fẹ padanu rẹ. Amọ nipa nini ero lati pa nkan yi mọ fun ara rẹ, o padanu ẹmi rẹ pẹlu awọn ara Sodomu ati Gomora, bi o tilẹ jẹ wipe eyi kọ ni ifẹ Ọlọrun fun un.
Jesu Oluwa wa wa lo nkan wọnyi lati kilọ fun awa naa lori iha ti o yẹ ki a kọ si opin aye yi at idajọ Ọlọrun ti o n bọ. O sọ fun wa wipe, “Ranti aya Lọti.” Kini idi? Idi ni pe, gẹgẹ bi aya Lọti ti ri aanu ati ojurere Ọlọrun gba fun igbala rẹ ni asiko ti a n ṣe idajọ Sodomu ati Gomora ni awọn naa ti a gba Jesu gbọ ti ṣe ri aanu ati ojurere Ọlọrun gba fun igbala ati atunbi wa sinu ijọba ayeraye Ọlọrun. Wayi o, gẹgẹ bi aya Lọti ṣe nilo lati sa asala fun ẹmi rẹ lalai bojo wẹyin ni awa naa ṣe nilo lati sa asala fun ẹmi wa ninu aye ẹṣẹ yi lailai boju wẹyin. Awa naa nilo lati yọ ọkan wa patapata kuro ninu gbogbo nkan ti aye yi ti o le fi aye wa ati ọkan wọn sinu ijamba ayeraye. A ko gbọdọ ṣe kògbóná-kòtutù, ẹsẹ kan ninu aye, ẹsẹ kan ninu ijọba Ọlọrun. Ko gbọdọ si ohunkohun ti a o ka si babara ju ọkan wa lọ, debi wipe a o titori rẹ bẹrẹ si ni woye pe boya ka boju wẹyin dipo ki a ma fi tọkantọkan tẹle Jesu. Aijẹbẹ, o ma ṣeeṣe ki ewu ti o wu aya Lọti wu awa naa.
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Ewu ti o wu aya Lọti ko ni i ṣe pẹlu aigbagbọ ninu Ọlọrun tabi ainibẹru rẹ. Dipo eyi, o ni i ṣe pẹlu aimọkan-kuro ninu nkan ti o le ṣe ipalara fun ẹmi rẹ. Nibakanna, nkan ti yoo jẹ ki ọpọ naa padanu ijọba Ọlọrun le ma ni i ṣe pẹlu aigbagbọ ninu Jesu. O le ni i ṣe pẹlu aimọkan-kuro ninu awọn nkan ti aye yi ti o le ṣe ijamba fun ọkan wa. A wa nilo lati ṣe idamọ awọn nkan naa ti o n jẹ ki bojuwẹyin lati dẹṣẹ tabi lati tẹ ẹran ara wa lọrun dipo ki a ma fi gbogbo ọkan wa tẹlẹ Jesu. Aijẹbẹ, awọn nkan wọnyi le gba ijọba ọrun danu kuro lọwọ wa. Idi niyi ti a si ṣe paṣẹ fun wa ninu Iwe mimọ bayi: “Nitori naa bi a ti fi ikuukuu awọn ẹlẹri to bayii yi wa ka, ẹ jẹ ki a pa ohun idiwọ gbogbo ti si apakan, ati ẹṣẹ ti o rọrun lati di mọ wa, ki a si maa fi suuru sure ije ti a gbe ka iwaju wa, Ki a maa wo Jesu Olupilẹsẹ ati alaṣepe igbagba wa; ẹni nitori ayọ ti a gbe ka iwaju rẹ ti o farada agbelebuu laika itiju si, ti o si joko lọwọ ọtun itẹ Ọlọrun.” (Hébérù 12:1-2)
ÌBÉÈRÈ
– Ki ni o ṣe pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi?
Lati ọwọ Johnson O. Lawal
Láti ọwọ́ Johnson O. Lawal
Copyright © 2023 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07025105978)
ÀKỌ́RÍ: MÁ ṢE ÀÌNÁNÍ Ẹ̀BÙN Ẹ̀MÍ RẸ | ỌJỌ́RÚ 19, AGẸMỌ 2023
ÀKỌ́SÓRÍ: “Ma ṣe ainani ẹbun ti n bẹ lara rẹ, eyi ti a fi fun ọ nipa isọtẹlẹ pẹlu igbọwọle awọn alagba.” (1Tímótì 4:14)
Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ
Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, gbogbo awọn ti o jẹ ọmọ Ọlọrun nipa didi atunbi ninu Jesu Kirisiti ni o ni ẹbun ẹmi kan tabi omiran. Pọọlu tilẹ fi idi eyi mulẹ nigba ti o sọ wipe, “Ṣugbọn a n fi ẹbun Ẹmi fun olukuluku eniyan lati fi jere.” (1Kọ́ríntì 12:7) Awọn wo n a fun ni ẹbun Ẹmi mimọ? Olukuluku ọmọ Ọlọrun ti Ẹmi rẹ n gbe inu rẹ ni a fi fun. Ki si ni idi ti a ṣe fi fun wọn? A fi fun wọn fun ere ati ilọsiwaju awọn ti o wa ninu aye wọn, paapaa-julọ awọn ọmọ Ọlọrun ti wọn n jijọ ṣe pọ. Ara idi si ni yi ti a fi gbọdọ ma ṣe amulo ẹbun Ẹmi yowu ti a ti ri gba, gẹgẹ bi Pọọlu ti ṣe jẹ ki o ye Timoti ninu abala lẹta rẹ ti a fẹ gbe yẹwo ninu ẹkọ yi. Adura mi si ni pe bi a ti ṣe n gbe awọn nkan wọnyi yẹwo, okun ati isọji yoo ba ọkan ti awa naa lati bẹrẹ si ni ṣe amulo ti o peye gbogbo ẹbun Ẹmi ti a ti ri gba lati ọwọ Ọlọrun.
MÁ ṢE ÀÌNÁNÍ Ẹ̀BÙN Ẹ̀MÍ RẸ
Ki wa ni Pọọlu sọ fun Timoti nipa lilo ẹbun Ẹmi rẹ? Awọn nkan ti o sọ fun nipa eyi ninu awọn lẹta rẹ mejeji ti o kọ si to melokan. Amọ eyi ti a fẹ wo ni o wa ninu lẹta rẹ akọkọ si, ori ikẹrin, eyi ti o ka bayi: “Ma ṣe ainani ẹbun ti n bẹ lara rẹ, eyi ti a fi fun ọ nipa isọtẹlẹ pẹlu igbọwọle awọn alagba.” (1Tíḿotì 4:14) Ki ni itunmọ ki a ṣe ainani nkan? O tunmọ si pe ki a ma ka nkan naa si bi o tilẹ je wipe nkan ti o yẹ ki a naani tabi mu ni pataki ni.
Nitorina, nipa sisọ fun Timoti pe ki o ma ṣe ainani Ẹbun ẹmi rẹ, o jasi pe o ye ki a naani ẹbun Ẹmi yowu ti a ba fun wa. O yẹ ki a mu ni pataki. Ki si ni idi ti o fi yẹ ki a mu ni pataki tabi naani rẹ? Akọkọ, o yẹ ki a mu ni pataki nitoripe Ọlọrun ni O fi fun wa. Ti a ba si naani Ọlọrun ninu aye wa, o yẹ ki a naani ohunkohun ti O ba fun wa pẹlu. A ri wipe bi a ba ti ṣe ka awọn eniyan si to ni a ṣe ma n ka awọn nkan ti wọn ba fun wa si to. Idi niyi ti a ṣe le e ma fi awọn nkankan ta awọn miran lọrẹ. Awọn ti wọn fun wa ni awọn nkan wọnyi ṣe pataki gidigidi si wa. Nitorina, bi ẹbun yowu ti wọn fun wa ti ṣe le kere to, ko ni rọrun fun wa lati fun ẹlomiran gẹgẹ bi ẹbun tabi nkan amuṣere. Mo wa sọ eyi lati jẹ ki a ri wipe ti a ba naani Ọlọrun ninu aye wa, o di dandan ki a naani ẹbun Ẹmi rẹ yowu ti O fun wa.
Idi keji ti a fi gbọdọ naani awọn ẹbun Ẹmi wa ni pe ajigbese ni wa nitori awọn ẹbun yi. Ọlọrun, bi a ti ṣe sọ siwaju, fun wa ni awọn ẹbun Ẹmi rẹ yi fun ere gbogbo araye ni. O fun wa ni awọn ẹbun yi fun itusilẹ wọn ati idagbasoke ati igberusi wọn ninu ifẹ rẹ ni. Ọlọrun fun wa ni awọn ẹbun yi ki O ba le ma ti ipasẹ wa mu ifẹ rẹ ṣẹ ninu aye yi ni. Nitorina, ti a ba kọ ti a ko lo awọn ẹbun yi tabi ti a n ṣi wọn lo, a jẹ wipe a ko naani wọn niyẹn. O si wa di dandan ki Ọlọrun bi wa lọjọ kan. Idi niyi ti Pọọlu fi sọ fun awọn ara Romu ninu lẹta rẹ si wọn pe, “Nitori mo jẹ ajigbese si Giriki ati si awọn alaigbede ti ki i ṣe Giriki, si awọn ọlọgbọn ati si awọn aṣiwere. Nitori idi eyi ni mo ṣe n lakaka lati wa si Romu ati lati fi gbogbo agbara mi waasu iyinrere Ọlọrun si i yin.” (Rómù 1:14-15)
Idi kẹta ti a fi gbọdọ naani awọn ẹbun Ẹmi wa ni pe awọn ẹbun Ẹmi yi le di yẹpẹrẹ lọwọ wa, ki Ọlọrun ma le ri lo mọ nipasẹ wa. Fun apẹẹrẹ, ẹbun ti Ọlọrun fun Samusoni pada di yẹpẹrẹ lọwọ rẹ nitoripe ko naani rẹ ati iwulo rẹ to. Lotitọ, Ọlọrun ko gba ẹbun yi lọwọ rẹ. Amọ, ẹbun naa ko pada wulo fun lati mu gbogbo ifẹ Ọlọrun ṣe lati ọwọ rẹ. Nitorina, ti awa naa ko ba naani iwulo ẹbun Ẹmi wa ati awọn nkan ti Ọlọrun fẹ lo fun, ti a si n ṣe bi o ti ṣe wu wa pẹlu aye wa, o ṣeeṣe ki ẹbun yi pada di yẹpẹrẹ ni ọwọ wa.
Awọn ọna wo wa ni a le gba lati fi han pe a naani awọn ẹbun Ẹmi wa. Pataki lara awọn ọna naa ni iwọnyi:
– Nipa dida ẹbun yowu ti a ni mọ: Ọkan lara idi ti Pọọlu ṣe sọ fun Timotiu pe ki o ma ṣe alainaani ẹbun Ẹmi rẹ ni pe o mọ daju pẹ arakunrin yi mọ ẹbun Ẹmi rẹ. Ki si ni ẹbun ẹmi rẹ? Bi a ko tilẹ sọ tààrà-táárá ninu bibeli, awọn akọsilẹ ti a ri ninu rẹ fi ye wa pe ara awọn ẹbun Ẹmi Timotiu ni ẹbun ikọni. Fun apẹẹrẹ, nkan ti Pọọlu kọkọ sọ fun ki o to sọ fun pe ki o ma ṣe ainaani ẹbun Ẹmi rẹ ni pe, “Titi emi o fi de, maa fiyesi kikawe ati igbani-niyanju ati ikọni.” (1Tìmótíù 4:13) Nitorina, Timotiu mọ ẹbun tabi awọn ẹbun Ẹmi rẹ. Pọọlu tilẹ tun jẹ ki o ye wa pe awọn isọtẹlẹ kan ti waye ri ti o jẹ ki Timotiu ati awọn ọmọ Ọlọrun miran mọ pe a fun ni awọn ẹbun Ẹmi kan. Ẹbun Ẹmi ti eniyan ba wa mọ ni o le naani. Ko le naani ẹbun Ẹmi ti ko ba mọ. Niwọn igba ti a si ti wa fi ye wa pe gbogbo wa ni a ni ẹbun Ẹmi, o kere ju ẹyọkan, pataki lara awọn nkan ti yoo fihan pe a naani awọn ẹbun Ẹmi yi ni ki a lepa lati mọ wọn. O wa ṣeni laanu wipe ọpọ ti o pe ara wọn ni ọmọ Ọlọrun ni ko mọ ẹbun Ẹmi wọn. Ki si ni idi? Wọn ko naani awọn ẹbun yi. Wọn ko ka wọn si. Wọn ko bikita boya Ọlọrun ri wọn lo nipasẹ awọn ẹbun yi lati mu ifẹ rẹ wa si imuṣẹ tabi ko ri wọn lo. Ti o ba ka Ọlọrun si, ti o si ka awọn ẹbun ti O fun ọ si, o di dandan ki o lepa lati mọ wọn. Si wa ma wo, gbogbo awọn ti o ba mura lati mọ ẹbun Ẹmi ti Ọlọrun fun wọn ni o di dandan ki wọn mọ wọn.
– Lilo ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun: Ki ni ifẹ Ọlọrun fun wa ni lilo awọn ẹbun Ẹmi rẹ? Ifẹ rẹ ni pe ki a lo awọn ẹbun Ẹmi yi fun itusilẹ, igberusi ati idagbasoke awọn eniyan (1Kọ́ríntì 12:7; 1Kọ́ríntí 14:12). Ifẹ rẹ ni pe ki a lo wọn lati ṣe e logo (1Pétérù 4:10-11). Ifẹ rẹ ni pe ki a lo pẹlu igbẹkẹle ninu agbara rẹ nikan dipo ninu ọgbọn ori wa tabi imọ wa (2Kọ́ríntì 3:5-6; Fílípì 3:3; 1Pétérù 4:11). Ifẹ rẹ si tun ni pe ki a lo awọn ẹbun Ẹmi yi lati ṣe awọn eniyan loore lọfẹ, niwọn igba ti o jẹ wipe awa naa ri wọn gba lọfẹ ni (Mátíù 7:8). Ti a ba wa naani Ọlọrun ti O fun wa ni awọn ẹbun yi, nṣe ni a o ma lepa lati lo wọn ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ dipo ifẹ ara wa. Ko wa si bi eniyan ti le sọ pe oun ka ẹbun Ẹmi oun si to, ti ko ba ti lo ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun, bi igba ti ko naani ẹbun naa ni. Nitoripe niwọn igba ti a ko ba ti lo ẹbun Ẹmi wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun, Ọlọrun ko ni le ri lo lati mu ifẹ rẹ ṣẹ ninu aye wa ati ninu aye awọn ti o wa ni awujọ wa ni ọna ti o peye. Nitorina, ti o ba ka Ọlọrun si, ti o si fẹ ki ifẹ rẹ jẹ mimu ṣẹ ninu aye yi nipa ẹbun ti O fun ọ, wa lepa lati mọ gbogbo ifẹ rẹ fun ọ ni lilo ẹbun naa.
– A gbọdọ ma a lo pẹlu itara ti o ga: Pọọlu sọ wipe, “Nitori mo jẹ ajigbese si Giriki ati si awọn alaigbede ti ki i ṣe Giriki, si awọn ọlọgbọn ati si awọn aṣiwere. Nitori idi eyi ni mo ṣe n lakaka lati wa si Romu ati lati fi gbogbo agbara mi waasu iyinrere Ọlọrun si i yin.” (Rómù 1:14-15) Eyi n fi han wa pe ti oye idi ti Ọlọrun ṣe fun wa ni awọn ẹbun Ẹmi rẹ ba ye wa, o di dandan ki a ma fi itara lo wọn. Ti a ba ni oye nitooto pe ajigbese ni a jẹ nitori awọn ẹbun ti a fi fun wa, o didan ki a bẹrẹ si ni fi itara lo wọn fun awọn ti Ọlọrun fẹ ti ipasẹ wa ṣe ni oore. Eyi yoo si fi han pe a naani ẹbun naa.
– A gbọdọ ma a lo, boya asiko wọ fun wa lati lo tabi ko wọ: Pọọlu sọ eyin fun Timoti ninu lẹta rẹ keji si: “Waasu ọrọ na, ṣe aisinmi ni akoko ti o wọ, ati akoko ti ko wọ…” (2Tímótíù 4:2) Pẹlu nkan ti o sọ yi, a ri wipe ko ki i ṣe igba gbogbo naa ni yoo rọrun fun wa lati lo ẹbun Ẹmi wa lati ṣe iṣẹ yowu ti Ọlọrun ba fẹ tipasẹ rẹ ṣe. Ti a ba wa naani ẹbun naa ati nkan ti Ọlọrun le lo fun, a ko ni ma fi igba gbogbo reti pe ki nkan rọrun tabi wọ fun wa ki a to le lo ẹbun yi. A ri awọn asiko ti Jesu ati awọn ọmọ ẹyin rẹ ko ri aye jẹun tabi simi nitoripe wọn fẹ lo ẹbun ti Ọlọrun fun wọn lati tun aye awọn eniyan ṣe. Eyi ko tunmọ si pe ki a ma sinmi daradara tabi jẹun to. Ṣugbọn ẹni ti o ba n fi igba gbogbo wa aye ti o wọ ki o to lo ẹbun Ẹmi rẹ ko naani ẹbun Ẹmi naa niyẹn. (Wo: Máàkù 6:30-34; Jòhánù 4:4-43)
– A gbọdọ lepa lati tayọ ni lilo ẹbun naa: Pọọlu sọ eyi fun wa lori ṣiṣe amulo ẹbun Ẹmi wa: “Bẹẹ si ni ẹyin, bi ẹyin ti ni itara ẹbun Ẹmi, ẹ maa ṣe afẹri ati maa pọ si i fun idagbasoke ijọ.” (1Kọ́ríntì 14:12) Ṣe o ri bayẹn? Pọọlu sọ wipe nṣe ni o yẹ ki a ma pọ si tabi tayọ si ni lilo ẹbun ẹmi wa. A ko gbọdọ rẹwẹsi rara ni lilo tabi ki a ma lo ni ọna ti o peye to. Eyi wa jasi pe a gbọdọ ṣi oju wa silẹ lati ri awọn anfaani ati ọna ti a le gba lo ẹbun Ẹmi yowu ti a ba ni lati mu ifẹ Ọlọrun ṣẹ ninu aye wa ati ninu aye awọn ti Ọlọrun fẹ lo wa fun. Idi ni yi ti Pọọlu, fun apẹẹrẹ, ṣe kọ oniruuru lẹta si awọn ọmọ Ọlọrun lati kọ wọn ni ifẹ rẹ nigba ti ko si aye fun lati lọ si ọdọ wọn. Idi naa si ni yi ti a n ṣe n ṣe atẹjade ọrọ Ọlọrun, ti a n ṣe akasilẹ rẹ ati ti a si tun ṣe n lo awọn ẹrọ redio, tẹlifisan ati ayelujara lati polongo ọrọ Ọlọrun. Nṣe ni a n wa ọna lati pọ si ninu awọn ẹbun Ẹmi wa lati kọni, lati waasu Jesu Kirisiti ati lati tu awọn eniyan silẹ kuro ninu ide eṣu. O wa yẹ ki iwọ naa bẹrẹ si ni gbadura pe ki Ọlọrun ṣi ọ ni iye lati ri awọn ọna ti o le gba pọ si tabi tayọ ni lilo ẹbun Ẹmi rẹ. Eyi yoo fi han pe o naani ẹbun naa ninu aye rẹ.
– A gbọdọ yago fun ohunkohun ti o le sọ ẹbun naa di yẹpẹrẹ: Ki ni idi ti Samusoni ṣe sọ aṣiri ẹbun agbara ti Ọlọrun fun fun aṣekupani obinrin ni, Dẹlila? Ainani ẹbun Ẹmi yi to ni. O mọ pe a fun oun ni ẹbun yi lati gba awọn eniyan rẹ la ni. Nitorina, ti igbala awọn eniyan rẹ kuro lọwọ awọn Filisitini ba ṣe iyebiye si gidigidi ni, ko ba ma ti fi aye gba ohunkohun ti o le pa ina ẹbun naa ninu aye rẹ. Ṣugbọn o fi aye gba, o si tipasẹ eyi sọ ẹbun naa di yẹpẹrẹ ati alaiwulo ninu aye rẹ. Ti awa naa ba ka ẹbun Ẹmi ti a fun wa ati iwulo rẹ fun Ọlọrun si, nṣe ni a o yago fun ohunkohun ti o ba le sọ di yẹpẹrẹ tabi alaiwulo ninu aye wa. Ara awọn nkan naa si ni agbere, ilara, imẹlẹ, ojukokoro ati bẹẹbẹẹ lọ. (Wo: Àwọn Onídájọ́ 13-16)
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Ọlọrun fun wa ni oniruuru ẹbun Ẹmi lati le lo wa fun ogo rẹ ati lati le mu ifẹ rẹ ṣe laye yi. Amọ, niwọn igba ti a ko ba naani awọn ẹbun yi, Oun ko ni le ri wa lo bi o ti tọ ati bi o ti yẹ. Eyi yoo si wa tunmọ si pe a ko naani Oun funrarẹ ninu aye wa. Iha wo wa ni Ọlọrun yoo kọ si ẹni ti ko ba naani rẹ? Eyi kọja afẹnusọ. Nitorina, gẹgẹ bi Pọọlu ti ṣe sọ fun Timotiu pe ko ma ṣe ainaani ẹbun Ẹmi rẹ bẹẹ naa ni Ẹmi Ọlọrun n sọ fun awọn naa loni pe ki a ma ṣe alainaani awọn ẹbun Ẹmi wa.
ÌBÉÈRÈ
– Yatọ si awọn ti a mẹnuba ninu ẹkọ yi, njẹ o le sọ awọn ọna miran ti a le gba fihan pe a naani awọn ẹbun Ẹmi wa.
– Ki ni o ṣe pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi?
Láti ọwọ́ Johnson O. Lawal
Copyright © 2023 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07025105978)
MÁ ṢE PA INÁ Ẹ̀MÍ | ÀYỌKÀ: 1TẸSALÓNÍKÀ 5:19 | ỌJỌ́RÚ 21, ÒKÚDÙ 2023
ÀKỌ́SÓRÍ: “Johanu si dahun o si wi fun u pe, Olukọ, awa ri ẹnikan o n fi orukọ rẹ le awọn ẹmi eṣu jade; awa si da a lẹkun, nitori ti ko ba wa tọ ọ lẹyin.” (Luku 9:49)
Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ
Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ko ki i ṣe gbogbo igba naa ni awọn apọsiteli Kirisiti ti wọn n n tẹle kaakiri ma n gbe igbesẹ tabi ṣe awọn nkan ti o wa ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ. A ri awọn igba ti o jẹ wipe ọrọ wọn, ero wọn tabi iṣeṣi wọn tako ifẹ rẹ, bi o tilẹ jẹ wipe wọn ko mọ-ọn-mọ tako ifẹ rẹ. Ara awọn ọna ti wọn si ti gba tako ifẹ rẹ ri ni nipa pipa ina ẹmi tabi ina itara awọn miran lati sin in, lati ṣiṣẹ fun tabi lati ri nkan gba lọwọ rẹ. Ṣe Jesu wa n wo wọn niran ni awọn asiko yi bi? Rara o! A ri wipe gbogbo igba ti awọn apọsiteli yi sọrọ tabi wuwa lodi si ifẹ rẹ ni O ba wọn wi, ti O si pe akiyesi wọn si nkan ti ko dara tabi tọna nipa nkan ti wọn ṣe. O wa yẹ ki awa naa, gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun ati ọmọlẹyin Kirisiti, kẹkọ lara awọn ikilọ ati ibawi ti awọn apọsiteli yi ti gba sẹyin, ki a ma ba ṣe iru aṣiṣe ti wọn ṣe, ki a si fi ara wa si ipo ẹni ti o n ba iṣẹ Ọlọrun jẹ. Idi si niyi ti ẹkọ ti a fẹ kọ yi fi da lori kí a má pa iná ẹ̀mí.
MÁ ṢE PA INÁ Ẹ̀MÍ
Wayi o, ki ni itumọ ki a pa ina ẹmi? Njẹ o tilẹ ṣeeṣe fun wa, gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun, lati pa ina ẹmi? Ti ko ba ṣeeṣe lati pa ina ẹmi, a ko ni kilọ fun wa ninu bibeli lati ma pa ina yi. Iwọ naa wo ikilọ Pọọlu si wa lori ọrọ yi: “E ma ṣe pa ina Ẹmi Mimọ.” (1Tẹsalóníkà 5:19) Eyi n fi han wa pe o ṣeeṣe fun wa lati pa ina Ẹmi mimọ, bi o tilẹ jẹ wipe ọmọ Ọlọrun ni wa, ti a si mọ Jesu. A ṣa a ri pe awọn ọmọlẹyin Jesu ti o wa ni ilu kan ti a n pe ni Tẹsalonika ni Pọọlu kọ lẹta ti o ti sọ ọrọ yi si, ko si ki i ṣe awọn alaigbagbọ. Ko tilẹ jẹ nkan ti o rọrun fun alaigbagbọ lati pa ina Ẹmi Mimọ, bi Jesu ti ṣe wi fun Pọọlu ni ọjọ ti O ba aye rẹ pade nigba ti o n lọ si ilu Damasiku (Ìṣe Àpọ́sítélì 26:14). Awọn ọmọ Ọlọrun, ti Ẹmi Mimọ rẹ n gbe inu wọn gan ni o ma n ṣaba gbe igbesẹ tabi fi ara wọn si ipo ti wọn yoo ti pa ina Ẹmi yi.
Ṣugbọn ki a to le tẹsiwaju lati wo bi a ti ṣe le pa ina Ẹmi Mimọ, a kọkọkọ gbọdọ ni oye itumọ ki a pa ina ẹmi. Ki si ni itumọ rẹ? O tunmọ si pe ki a ṣe nkan ti yoo di iṣẹ ti Ẹmi Ọlọrun fẹ tipasẹ wa tabi tipasẹ elomiran ṣe lọwọ, yala a mọ-ọn-mọ ṣe ni tabi a ko mọ-ọn-mọ ṣe. Eyi jasi pe ko ki i ṣe inu aye ẹlomiran nikan ni a tile pa ina Ẹmi Ọlọrun; a le pa a ninu aye ti ara wa pẹlu. Ọpọ ni o si n pa ina Ẹmi Mimọ ninu aye wọn ati ninu aye awọn ti o wa ni ayika wa nipa aini oye ọrọ Ọlọrun lori nkan ti wọn n ṣe ati awọn ewu ti o sorọ mọ.
Awọn ọna wo wa ni a le gba lati pa ina ẹmi? Awọn ọna ti a le gba pa ina ẹmi pọ jantirẹrẹ. Amọ a o mẹnuba melokan lara wọn ninu ẹkọ yi. Awọn naa si ni wọnyi?
– Ailoye: ọkan gbogi lara awọn nkan ti o le sọ wa di ẹni ti o n pa ina ẹmi ninu aye awọn miran ni ailoye ifẹ Ọlọrun ati ọna ti O n gba ṣiṣẹ. Ninu ẹsẹ akọsori wa, a ri wipe Johanu, ọkan ninu awọn apọsiteli akọkọ ti Jesu yan, pe akiyesi rẹ si nkankan ti o ṣe kayefi si wọn. Ki si ni? Wọn ri ẹnikan ti o n le ẹmi eṣu jade ni orukọ Jesu, wọn si wa fẹ da ẹni lẹkun. Ki ni idi? Ṣe nkan ti ọkunrin yi n ṣe ko tọna ni? O tọna. Ṣe awọn ẹmi eṣu ti o n le jade lorukọ Jesu ko jade ni? Wọn kuku n jade. Ki wa lo fa ti wọn ṣe fẹ da ọkunrin naa lẹkun? Idi ni pe ko ki i ṣe ara wọn. Ki wa ni Jesu sọ lori eyi? O sọ wipe, “Ma ṣe da a lẹkun mọ: nitori ẹni ti ko ba lodi si wa, o wa fun wa.” (Lúùkù 9:50) Njẹ o ri bayẹn? Wipe ẹnikan ko ki i ṣe ọmọ ijọ wa ko tabi pe ko ma mura bi a ti ṣe n mura tabi pe ko ma sọrọ bi a ti ṣe n sọrọ ko tunmọ si pe ko ki i ṣe ọmọ Ọlọrun tabi iransẹ rẹ. Ti oye eyi ko ba wa ye wa, o ṣeeṣe, ki a gbegi dana iru ẹni bẹ, ki a si pa ina Ẹmi Ọlọrun ti o n jo ninu aye wọn. A tun ri apẹrẹ miran ti o farapẹ eyi ninu iwe iyinrere ti Maaku, ori ikẹwa, lati ẹsẹ ikẹtala, ti o sọ pe, “Wọn si gbe awọn ọmọ-ọwọ tọ ọ wa, ki o le fi ọwọ kan wọn: awọn ọmọ-ẹyin rẹ si ba awọn ti o gbe wọn wa wi. Ṣugbọn nigba ti Jesu ri i, inu bi i, o si wi fun wọ pe, Ẹ jẹ ki awọn ọmọ kekere ki o wa sọdọ mi, ẹ ma si ṣe da wọn lẹkun: nitori tiwọn ni ijọba Ọlọrun.” (Máàkù 10:13-14) Ki ni idi ti awọn ọmọ ẹyin lọjọ yi ṣe ba awọn ti o n gbe awọn ọmọ-ọwọ tọ Jesu wa wi? Ailoye ifẹ Ọlọrun fun igbala awọn ọmọde. Ni oju ti wọn, bi igba ti wọn ba n yọ Jesu lẹnu ni wọn ka si. Ṣugbọn Jesu jẹ ki o ye wọn pe ti awọn ọmọde pẹlu ni ijọba Ọlọrun n ṣe. Nitorina, ti a ba ti bẹrẹ si ni le awọn ọmọ wa jina si ipade wa, yala nitoripe a ko fẹ ki wọn pariwo tabi di wa lọwọ, a ti n pa ina itara ati ifẹ si Ọlọrun ninu aye wọn niyẹn.
– Ikẹgan ẹbun Ẹmi: lẹyin igba ti Pọọlu sọ fun awọn ara Tẹsalonika lati ma pa ina ẹmi tan, nkan ti o sọ tẹle ni eyi: “Ẹ ma ṣe kẹgan awọn ti n sọtẹlẹ. Ṣugbọn ẹ dan gbogbo nnkan wo. Ẹ di eyi ti ṣe otitọ mu. Ẹ yẹra fun ohunkohun ti i ṣe ibi.” (1Tẹsalóníkà 5:20-22) Eyi n jẹ ki o ye wa pe ọkan pataki lara ọna ti a le gba pa ina Ẹmi Ọlọrun ninu aye wa tabi ninu aye awọn ẹlomiran ni ki a fi oju kere tabi fi ẹnu tẹnbẹlu awọn ẹbun ti Ẹmi rẹ fifun wọn. A si ri awọn ti ẹbun Ẹmi ti Ọlọrun fifun wọn ko jọ wọn loju. Nitorina, ko si bi anfaani ṣe pọ to fun wọn lati lo awọn ẹbun yi, wọn ko ni lo. Nṣe ni wọn yoo ma pa Ẹmi Ọlọrun ti O n kọ si wọn lati lo lẹnu mọ. Bakanna ni a ri awọn ti wọn ma n foju kere ẹbun ti Ọlọrun fun awọn miran tabi ti wọn ma n ni lọkan pe ẹbun kan ko tọ si awọn kan. Nitorina, ko si iru ara ti Ọlọrun le ma ti ọwọ yin da pẹlu ẹbun yin, irufẹ awọn wọnyi ko ni ka si nkan. Nṣe ni wọn yoo fi ẹnu yẹnpẹrẹ rẹ, ti wọn yoo si fi irẹwẹsi si wa lọkan. Idi niyi ti Pọọlu fi sọ pe ki a ma ṣe kẹgan isọtẹlẹ, yala nitoripe ko ba wa lara mu tabi pe ko wa lati ẹnu ẹni ti a nifẹsi. Dipo eyi, nṣe ni a ki ṣe agbeyẹwo rẹ boya o wa ni bamu pẹlu ifẹ Ọlọrun tabi ko wa ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ. Eyi ni yoo jẹ ki a mọ iru iha ti o yẹ ki a kọ si, dipo eyi ti a o fi fi irẹwẹsi sinu awọn ti Ọlọrun n lo, ti a o si jẹ ki wọn pa isẹ ti o gbe le wọn lọwọ ti. (Wo: 1Kọ́rínntì 12:14-26)
– Awawi: lẹyin ti Mose ti salọ kuro ni Ijibiti fun bi ogoji ọdun, Ọlọrun tọ ọ wa lati ran pada si Ijibiti lati gba awọn eniyan rẹ la kuro loko ẹru. Amọ nṣe ni ọkunrin n ṣe awawi. O si ṣe awawi debi pe inu bi Ọlọrun si, ti o si sọ fun pe Oun yoo ran Aaroni arakunrin rẹ pẹlu rẹ. Nigba ti o si wa lọ, bi a ti ṣe ran, Ọlọrun lo gidigidi ati ni ọpọlọpọ ọna debi pe orukọ rẹ ko le parẹ mọ lailai. Amọ ka wa sọ wipe Ọlọrun ko mu suuru ni nkọ? Njẹ ẹnikankan yoo ma sọrọ rẹ loni? Ọpọ ni o wa dabi Mose loni, ti awọn naa n fi gbogbo igba pana Ẹmi Mimọ ninu aye wọn nipa ṣiṣe awawi. Ti iru awọn wọnyi ko ba si ronupiwada ni kiakia, ki wọn si bẹrẹ si ni ṣe nkan ti Ọlọrun fẹ ki wọn ṣe, o ṣeeṣe ki O pa wọn ti, ki O si wa ẹlomiran ti yoo ṣe ifẹ rẹ. (Wo: Ẹ́kísódù 3-4)
– Ìmẹ́lẹ: Ara awọn ẹkọ ti owe iranṣẹ mẹta ti Jesu sọ kọ wa ni pe imẹlẹ ma n pa ina ẹmi. Lotitọ, owe yi ni i ṣe pẹlu nkan ti ara. Amọ Jesu sọ lati fi kọ wa ni nkan ti ẹmi ni. Bi O si ti ṣe fi ye wa ninu owe naa, niwọn igba ti a ba ti ya ọlẹ, ko si bi Ẹmi Ọlọrun ti ṣe le pese anfaani, ẹbun tabi nkan ini fun wa to lati ṣiṣẹ rẹ ti a o ṣe amulo ipese rẹ. Ọlẹ ni ọmọ ọdọ ti Oluwa rẹ fun ni talẹnti kan, eyi ti i ṣe ọpọlọpọ owo ni asiko naa, ti o si lọ bo mọlẹ. Nitoripe ọlẹ ni ni ko ṣe bikita lati ronu rara nipa awọn ọna ni o le gba ṣe amulo owo ọga rẹ, ki o si sọ di pupọ si. Ti awa naa ba si jẹ ọlẹ, ẹni ti ko fẹ nkankan ṣe, Ẹmi Ọlọrun ko tilẹ ni ni ohun lati sọrọ ninu wa debi pe yoo le ru wa soke lati ṣe nkan ti o fẹ ki a ṣe. (Wo: Mátíù 25; Lúùkù 19)
– Ẹ̀rù bíbà: Nkan miran ti owe iransẹ mẹta ti Jesu sọ tun kọ wa ni pe ẹru biba ma n pa ina ẹmi. Iranṣẹ ti Oluwa rẹ fun ni talẹnti kan, ti ko si lo, jẹ ki o ye ọga rẹ pe ẹru ki oun ma padanu owo yi ni o ba oun, ti oun ko si ṣe ṣe amulo rẹ. Ọpọ ọmọ Ọlọrun naa si ni ẹru ko jẹ ki wọn ṣe amulo awọn ẹbun Ẹmi inu aye wọn ati awọn anfaani lati ṣe amulo awọn ẹbun yi. Gbogbo igba ti Ẹmi Ọlọrun ba n ru wọn soke ni ibẹrubojo, ibẹru nkan ti awọn eniyan yoo wi tabi ti wọn le ṣe si wọn ko ni jẹ ki wọn gbe apa tabi gbe ẹsẹ. Nitorina, Ọlọrun ko ri wọn lo bi O ti ṣe fẹ lo wọn. Ti wọn ko ba si tete gbe ẹ̀rù wọn ju danu, ki wọn si ma fi gbogbo igba ranti pe Ọlọrun wa pẹlu wọn lati jẹ ki wọn ṣe aṣeyọri lori ohunkohun ti O ba gbe le wọn lọwọ, o ṣeeṣe ki O pa wọn ti lasiko kan, ki O si fi ẹlomiran ti yoo ṣe ifẹ rẹ dipo wọn. Pọọlu ba Timoti sọrọ lori eyi. O sọ fun pe ki o ma fi gbogbo igba ru ẹbun Ọlọrun ti o wa ninu aye rẹ soke. Ki si ni idi? Idi ni wipe Ọlọrun ko fun awọn ọmọ rẹ ni ẹmi ojo, ẹmi ibẹru, bi ko ṣe ẹmi ifẹ, ẹmi agbara ati ẹmi ikoara-ẹni-nijanu. Eyi n jẹ ki o ye wa pe ti Timoti ba kọ lati lo ẹbun ẹmi rẹ, ti o ba n fi gbogbo igba pana ẹmi, ko ni jẹ nitori pe Ọlọrun ko ṣe e yẹ to; dipo bẹ, yoo jẹ nitoripe o fi aye gba ẹmi ẹru lati di lọwọ. (Wo: 2Tímótì 1:6-7)
– Ìlara: bi mo ti ṣe sọ siwaju, ko ki ṣe inu aye ara wa nikan ni a ti le pa ina ẹmi; a le pa ninu aye awọn miran pẹlu. Ọpọ igba ni o si jẹ pe ninu aye awọn miran ni a ti ma n pa ina ẹmi ju. Ara ọna ti a si le gba pa ina ẹmi ninu aye awọn miran ni ki a ma ṣe ilara wọn. Sọọlu, fun apẹrẹ, ṣe ilara Dafidi, bi o tilẹ jẹ wipe Dafidi kere si pupọ ni ọjọ ori, ipo, ọla, ọrọ ati bẹẹbẹẹ lọ. Ki si ni idi? O ri wipe awọn eniyan tẹwọgba ọmọ yi bi akọni ọkọrin ju ohun tikararẹ lọ. Nitori ilara ti o si wa ni si i, gbogbo igbesẹ ti o wa ni arọwọto rẹ ni o gbe lati pa Dafidi run. Ti ko ba wa jẹ wipe Dafidi fi igbẹkẹle rẹ sinu Ọlọrun ni, ti o si ti kọ bi a ti ṣe n gba ara ẹni niyanju pẹlu ọrọ rẹ, nṣe ni ko ba sala patapata, ti ko si ni gbe igbesẹ mọ lati gba ipo ọba ti Ọlọrun ti da ororo le lori lati wa. A si ri ọpọ ti a ti pa ina Ẹmi wọn lọna kanna ninu ijọ nipasẹ ilara, yala lati ọdọ awọn adari ijọ wọn, adari ẹgbẹ wọn tabi awọn miran ti wọn fẹ le ma ṣe nkan ti wọn n ṣe. A ti fi ilara le awọn wọnyi kuro ninu ijọ Ọlọrun tabi le wọn jinna rere si ifẹ Ọlọrun fun aye wọn. Ti Ọlọrun ko ba wa ri ẹnikẹni lo lati gba irufẹ awọn wọnyi niyanju ati lati mu irẹwẹsi kuro lọkan wọn, o ṣeeṣe ki O ma ri wọn lo mọ titi akoko wọn yoo fi tan laye yi. Idi si niyi ti a fi gbọdọ ṣọra. Ẹni kọọkan wa ni o ni aye tirẹ ati ẹbun tirẹ ninu ijọba Ọlọrun. Nitorina ṣiṣe amulo ẹbun elomiran ko di wa lọwọ lati ṣe amulo ti wa. Ọna ti awọn miran si n gba ṣe amulo ẹbun ti wọn ko di wa lọwọ lati ṣe amulo ti wa, niwọn igba ti ko ba ti ta ko ifẹ Ọlọrun. Ti oye eyi ko ba wa ye wa, ilara le gba ọna yi wọnu aye wa, ki o si sọ wa di ẹni ti ẹsu yoo lo lati pa ina Ẹmi Mimọ ninu aye awọn miran. (Wo: 1Kọ́rínntí 12:18-20)
– Àìsí ìrànlọ́wọ́: ọna miran ti a tun le gba pa ina ẹmi ni kí á ma fi iranlọwọ dun awọn ọmọ Ọlọrun ti O n lo tabi ti o fẹ lo. Eyi le jẹ nipa ki a ma ni ọrọ iwuri lẹnu lati gbe wọn lọwọ soke, ki a ma ranti wọn ninu adura loore-koore tabi ki a ma fi owo ati awọn nkan ini wa ran iṣẹ iranṣẹ wọn lọwọ. Ọpọ loni ti Ọlọrun ko ba ma lo gidigidi ni ko ri lo rara. Ki si ni idi? Nigba ti irẹwẹsi fẹ gba ọkan wọn, boya nitori inunibini, idaamu iṣẹ tabi ailowo lọwọ, ko si ẹni ti yoo ran igbagbọ ati ifẹ wọn lọwọ. Nitorina irẹwẹsi gba ọkan wọn, ina ẹmi ti o n jo ninu wọn si ku. Awọn naa wa pada di ẹni ti a n bẹ ki wọn to wa si ipade awọn ọmọ Ọlọrun tabi ki wọn to sin Ọlọrun. Eyi ko dara rara. Lotitọ, a ko gbọdọ gbarale iranwọ owo, adura tabi ọrọ iwuri awọn eniyan lati sin Ọlọrun. Amọ awọn nkan wọnyi naa ni ipa ti wọn ma n ko lati jẹ ki ina ẹmi awọn ọmọ Ọlọrun ma fi igba gbogbo jo. Yatọ si iyẹn, Jesu funralarẹ ti pa a laṣẹ fun wa lati ma fi nkan ini rẹ ran ara wa lọwọ, paapaa julọ awọn ti o n dari wa, ti o n fi ọrọ rẹ bọ wa. O si jẹ ki a mọ wipe irufẹ iṣẹ rere bayi ti a ba ṣe ko ni lọ lai ni ere. Wa wo awọn akọsilẹ Pọọlu yi, ki o si ṣaṣaro lori wọn:
“Ẹyin paapaa si mọ pẹlu, ẹyin ara Filipi, pe ni ibẹrẹ iyinrere, nigba ti mo kuro ni Makedonia, ko si ijọ kan ti o fun mi ni iranlọwọ owo, bi ko ṣe ẹyin nikanṣoṣo.” (Fílípì 4:15)
“Ni atetekọ jẹ ẹjọ mi, ko si ẹni ti o ba mi gba ẹjọ ro; ṣugbọn gbogbo eniyan ni o kọ mi silẹ: adura mi ni ki a ma ṣe ka a si wọn ni ọrun.” (2Tímótì 4:16)
Ki ni eyi n fi ye wa? O n fi ye wa pe o ṣeeṣe ki Ọlọrun lo eniyan bi o ti ṣe lo Pọọlu, ki a si tun ri awọn asiko kan ti ko ni ri ẹnikẹni laarin awọn ọmọ Ọlọrun ti yoo gbe ni igbọnwọ. Ti ko ba wa ki i ṣe ẹni ti o ti pa ọkan rẹ pọ lati fi gbogbo aye rẹ sin Jesu, yala awọn eniyan fun ni iwuri tabi wọn ko fun ni iwuri, ṣe ko ni rẹwẹsi? Sibẹsibẹ, a si ri asiko ṣaaju igba yi ti Ọlọrun lo Titu fun lati tu u ninu ati lati gbe ni ọwọ soke (2Kọrinnti 7:5-7). Nitorina, iha ti a kọ si riran awọn ọmọ Ọlọrun ati awọn iranṣẹ rẹ lọwọ ni ipa pataki lati ko lori boya ina ẹmi wọn yoo ma fi igba gbogbo jo tabi yoo ku.
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
O wa yẹ ki a mọ wipe ewu wa fun wa ti a ba n pa ina Ẹmi awọn eniyan. Bẹẹni, ewu ti o ga ni o le wu ẹni ti o ba n di iṣẹ ti Ọlọrun n fẹ ṣe nipasẹ elomiran lọwọ tabi ti o ba n di awọn ti o n fi itara ṣafẹri Ọlọrun lọwọ lati sin in. Fun apẹẹrẹ, a ri ninu bibeli bi iransẹ ọba Isiraẹli kan ṣe di oku nitori pe o kẹgan isọtẹlẹ Wolii Eliṣa, ti o si fẹ pa ina igbagbọ ọba rẹ ninu ọrọ Ọlọrun. A tun ri bi ọkunrin kan ti a n pe ni Baa-Jesu ṣe di afọju nitoripe o gbiyanju lati pa ina ẹmi alakoso agbegbe kan ti Ọlọrun fẹ sọ di ẹni igbala nipasẹ iwaasu Pọọlu ati Banaba. Nitorina a nilo lati ṣọ ara wa gidigidi, ki a ma si ṣe jẹ ki eṣu lo wa lati pa ina ẹmi ẹnikẹni ni ọna yowu ti o le jẹ. (Wo: 2Àwọn Ọba 7; Ìṣe Àpọ́sítélì 13:6-12)
ÌBÉÈRÈ
– Njẹ ẹkọ yi wulo fun awọn ọmọ Ọlọrun bi?
– Ki ni pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi?
Láti ọwọ́ Johnson O. Lawal
Copyright © 2023 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07025105978)
ÀKỌ́RÍ: ṢÍṢE IṢẸ́ AJÍYÌNRERE – OBÌNRIN ARÁ SAMÁRÍÀ | ÀYỌKÀ: JÒHÁNÙ 4:3-42 | ỌJỌ́RÚ 07, ÒKÚDÙ 2023
ÀKỌ́SÓRÍ: ”Nigba naa ni obinrin naa fi ladugbo rẹ silẹ, o si mu ọna rẹ pọn lọ si ilu, o si wi fun awọn eniyan pe, Ẹ wa wo ọkunrin kan, ẹni ti o sọ ohun gbogbo ti mo ti ṣe ri fun mi: eyi ha le jẹ Kirisiti naa?”” (Johanu 4:28)
Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ
Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, pupọ julọ lara awọn ti o tọ Jesu wa fun ọrọ igbala, iwosan ati idande ni o wa lati ipasẹ awọn melokan ti o ti ni anfaani lati jẹ igbadun didara rẹ. Eyi si n jẹ ki o ye wa pe ti ọpọ ni awujọ wa loni naa yoo ba tọ Jesu wa fun itusilẹ tabi idande wọn, awa ti a ti tọ didara rẹ wo ni iṣẹ ti o pọ lati ṣe. A nilo lati ma fi gbogbo igba pe wọn tabi rọ wọn lati tọ ọ wa nipa lilo apẹrẹ aye wa tabi aye awọn miran ti o ti jẹ igbadun didara rẹ. Eyi si ni ẹkọ ti a fẹ kọ lati ara arabinrin kan ti Jesu pade ni ilu Samaria kan ti a n pe ni Sikari. Ki Ọlọrun si lo ẹkọ yi lati tun wa ṣe ni gbogbo ibi ti a ti n kuna lati jẹ ki O lo wa fun igbala awọn miran.
OBÌNRIN ARÁ SAMÁRÍÀ
Ta wa ni arabinrin Samaria ti ẹkọ yi da le lori ati wipe ọna wo ni Jesu gba pade rẹ? Bi a ti ṣe jẹ ki o ye wa ninu bibeli, irinajo kan ti Jesu n rin lo jẹ ki o ṣe alabapade arabinrin ti a n sọrọ rẹ yi? Iwọ naa wo diẹ lara nkan ti a sọ ninu bibeli nipa ipade yi:
“Nigba ti Oluwa mọ nipa eyi, O fi Judea silẹ, o si tun lọ si Galili lẹẹkan si. Oun si ni lati kọja laarin Samaria. Nigba naa ni o de ilu Samaria kan, ti a n pe ni Sikari, ti o sunmọ eti ilẹ oko ti Jakọbu ti fun Josẹfu, ọmọ rẹ. Kanga Jakọbu si wa nibẹ. Nitori pe o rẹ Jesu nitori irin rẹ, bẹẹ ni o joko leti kanga: o si jẹ iwọn wakati kẹfa ọjọ. Obinrin kan, ara Samaria si wa lati fa omi: Jesu wi fun un pe, fun mi mu. (Nitori awọn ọmọ-ẹyin rẹ ti lọ si ilu lati lọ ra onjẹ.) Obinrin ara Samaria naa sọ fun un pe, “Juu ni ẹ, obinrin ara Samaria ni emi. Eeti ri ti iwọ n beere ohun mimu lọwọ mi?” (Nitori ti awọn Juu ki i ba awọn ara Samaria ṣe pọ.)” (Johan 4:3-9)
Pẹlu akọsilẹ yi, a ri wipe Jesu kan nla ilu arabinrin yi kọja ni asiko ti wọn pade ni. A tun ri wipe akoko ti O pade arabinrin yi jẹ akoko ti o rẹ ẹ, ti o si yẹ ki o ma sinmi. Sibẹsibẹ, Jesu ṣe amulo asiko ti ko wọ naa lati ba arabinrin yi sọ awọn ọrọ ti o yi aye rẹ pada titi lailai. A tilẹ tun ri, ṣiwajusi ninu akọsilẹ Johanu lori ipade yi, pe nigba ti awọn ọmọ ẹyin Jesu ti o lọ ran ounjẹ de, ti wọn si fẹ ki o jẹun, nṣe ni O sọ fun wọn pe, “Onjẹ mi ni lati ṣe ifẹ ẹni ti o ran mi ati lati pari iṣẹ rẹ.” (Johanu 4:34)
O wa ṣe ni laanu pe ọpọ wa ni o ma n wa akoko ti o wọ lati ṣe iṣẹ Ọlọrun tabi iṣẹ ijere-ọkan. Ṣugbọn awọn kan wa ti o jẹ wipe Ọlọrun ko le ri aye wọn yi pada niwọn igba ti a ba n wa akoko ti o wọ lati jere ọkan wọn. Bẹẹ gẹgẹ ni o si ti ṣe ri pẹlu arabinrin ti a n sọ ọrọ rẹ yi. Akoko ti o wa pọn omi ni ibi kanga ti Jesu ti pade rẹ ki i ṣe akoko ti o wọ. O jẹ iwọn wakati kẹfa ọjọ. Eyi jasi pe asiko ti oorun mu gidigidi ni, ti ọpọ ko si ni fẹ jade lati ma wa omi kiri.
Ki lo wa fa ti arabinrin yi fi wa omi wa ni akoko yi? Irufẹ eniyan ti o jẹ ni o fa a. A ri wipe a ko darukọ arabinrin yi ninu iwe Johanu rara. O tunmọ si pe a fi orukọ bo ni aṣiri ni. Ṣugbọn iru eniyan wo gan ni o jẹ? Bi a ti ṣe ri ninu akọsilẹ yi, obinrin yi jẹ ẹnikan ti o ṣoro lati ba da nkan pọ. Fun apẹrẹ, nigba ti Jesu ri, ti O si tọrọ omi lọwọ rẹ, aroye ni o nṣe, aroye wipe awọn Juu ko ki i ni nkankan ṣe pẹlu awọn ara Samaia ni o n ṣe. Eyi jasi pe ko fẹ fun ni omi rara.
Ṣe Jesu ko wa mọ pe ara Samaria ni obinrin yi ni ki O to bere omi lọwọ rẹ? O mọ! Ti a ba tilẹ fẹ sọ otitọ, Jesu gan an, gẹgẹ bi Juu, lo yẹ ki o korira a ti ba arabinrin yi i ṣọrọ. Sibẹsibẹ, nitori ki o ba le di ẹni igbala, Jesu ko fi ti aṣa tabi ẹsin ṣe. Idi niyi ti O fi bere omi lọwọ rẹ, ki O ba le ni anfaani lati ba sọ ọrọ iye ati igbala. Ṣugbọn nitoripe obinrin yi jẹ ẹnikan ti ko ko eniyan mọra, ẹnikan ti jẹ onjijangbọnm, ko ṣetan lati fun Jesu lomi.
Sibẹsibẹ, Jesu ko wo ọrọ ẹnu rẹ. Dipo eyi, O jẹ ki o ye pe Oun ni omi iye, omi ayeraye ti Oun le fun un mu, ti orungbẹ ko si ni gbẹ mọ lailai (Jòhánù 4:10-15). Awada ni obinrin yi pe ọrọ naa. Oun naa si tẹsiwaju lati ma gbe Jesu gun ori ẹṣin ayan. Amọ, nigba ti Jesu, nipa ifihan ẹmi Ọlọrun, gbẹnu le ọrọ aye obirin yi, oye bẹrẹ si ni ye pe eniyan lasan kọ ni oun n ba sọrọ. Wo nkan ti a sọ nipa eyi:
“Jesu wi fun un pe, “Lọ pe ọkọ rẹ, ki o si pada wa si ihin yii.” Obinrin naa dahun, o si wi fun un pe, “Emi ko ni ọkọ.” Jesu wi fun un pe, Iwọ dahun daradara pe, emi ko ni ọkọ: Nitori ti iwọ ti ni ọkọ marun-un ri; ọkunrin ti iwọ si ni ba yii ki i ṣe ọkọ rẹ. Ohun ti o ṣeṣẹ sọ tan yii, otitọ ni.”” (Johanu 4:16-18)
Ṣe o ri bayẹn? Arabinrin yi ti ni ọkọ marun ṣaju asiko ti o pade Jesu yi. Yatọ si eyi, ọkunrin ti o wa ni ọdọ rẹ ni akoko naa ko ki i ṣe ọkọ rẹ rara – wọn kan jọ n ba ara wọn sun ni. O wa tunmọ si pe arabinrin yi funrarẹ ni lọwọ, o di sẹru, ko si le jẹ ẹnikan ti awọn eniyan yoo fẹ ba ni nkan ṣe pọ ninu ilu rẹ. Abalajọ ti o fi wa pọnmi lọsan gangan, ninu oorun ti o gbona girigiri. Ko fẹ ki awọn eniyan ri oun debi pe wọn yoo ma yọ suuti ẹnu si. Bawo ni Jesu ṣe wa mọ awọn nkan wọnyi nipa rẹ? Nipasẹ ifihan Ẹmi Mimọ ni. Eyi n jẹ ki o ye wa pe a nilo ifihan Ẹmi Ọlọrun ni igba miran lati le tu awọn kan silẹ kuro ninu ide Eṣu ati ide ẹṣẹ.
Wayi o, pẹlu bi a ti ṣe jẹ ki obinrin yi mọ pe aṣiri rẹ ko bo rara ati pe Ọlọrun mọ ohun gbogbo nipa rẹ, eniyan yoo ro pe nṣe ni o yẹ ki o rẹ ọkan rẹ silẹ ni kiakia, ki Jesu ba le tun aye rẹ to. Amọ ko ṣe bẹ rara. Nṣe ni o yi ọrọ pada kuro lori eyi ti o ni i ṣe pẹlu aye rẹ, ti o si bẹrẹ si ni sọrọ ẹsin. Ṣibẹsibẹ, Oluwa ko ba binu rara. Dipo bẹẹ, nṣe ni O bẹrẹ si ni fun ni oye nipa ọna ti o tọ lati sin Ọlọrun ati irufẹ ẹni ti Oun jẹ. Awọn ọrọ yi si wọ akinyẹmi ara rẹ debi wipe o fi ladugbo rẹ silẹ lati lọ pe awọn ara ilu rẹ wa lati gbọ Jesu. (Wo: Johanu 4:19-29)
Bawo wa ni awọn ara ilu arabinrin ti a le pe oníjàngbọ̀n tabi oníjàgídíjàgan eniyan ṣe gba ọrọ rẹ? Iwọ naa wo nkan ti a kọ silẹ nipa eyi:
“Ọpọ awọn ara Samaria lati ilu naa si gba a gbọ nitori ọrọ obinrin naa, o jẹrii pe, o sọ ohun ti mo ti ṣe fun mi. Nitori naa, nigba ti awọn ara Samaria wa sọdọ rẹ, wọn tu u pe, ki o ba wọn jokoo: o si gbe ibẹ ni ọjọ meji. Awọn ọpọlọpọ si gbagbọ nitori ọrọ rẹ; Wọn si wi fun obinrin naa pe, Kii ṣe nitori ọrọ rẹ ni awa ṣe gbagbọ: nitori ti awa tikarawa ti gbọ ọrọ rẹ, awa si mọ pe, nitootọ, eyi ni Kirisiti naa, Oluwagbala araye.” (Jòhánù 4:40-42)
Njẹ o ri bayi? Ọpọ awọn ara ilu obinrin yi ni o gba ọrọ rẹ gbọ, ti wọn si ti ipasẹ rẹ di alabapin ninu iṣẹ iranṣẹ Jesu. Ki lo fa ti wọn fi gba ọrọ rẹ gbọ, bi o tilẹ jẹ wipe ẹnikan ti ko fẹ ni nkankan ba ẹnikẹni i ṣe ni? O gbọdọ jẹ wipe o ba wọn sọrọ nipa Jesu pẹlu idaniloju ati igboya. Bẹẹni, o ni lati jẹ wipe arabinrin yi gbe gbogbo ohun ti o ni i ṣe pẹlu ibinu, asọ ati arankan rẹ si awọn ara ilu yi ju danu, ti o si bẹrẹ si ba wọn sọrọ nipa iriri rẹ pẹlu ọkunrin ajeji kan ti o ba pade ati nipa ifura rẹ pe o ṣeeṣe ki ọkunrin naa jẹ Mesaya ti awọn n reti. O tun ni lati jẹ wipe awọn ara ilu arabinrin yi naa n ti n pongbẹ fun Mesaya wọn.
Wayi o, ti arabinrin yi ti awọn eniyan ko sọrọ rẹ daradara ninu ilu rẹ ba le ṣe iṣẹ ajinyinrere ni ọjọ naa ti o pade Jesu, ko yẹ ki a ri ẹni naa lara awa ti a ti gba Jesu ni Oluwa ati Olugbala wa ti ko yẹ ki o ma le ṣe iṣẹ yi laarin awọn eniyan wa. Ki ni a nilo lati le ṣe eyi? Njẹ a nilo lati mọ gbogbo ẹṣẹ bibeli ki a to le ṣe? Rara o! Arabinrin Samaria yi ko nilo lati mọ gbogbo nkan ti o wa ninu bibeli ki o to le mu iyinrere nipa Jesu tọ awọn eniyan rẹ lọ. Ko si nilo ki iwa rẹ dara, bi o tilẹ jẹ wipe ki a ni iwa ti o dara le ran wa lọwọ lati ṣe iṣẹ ajinyinrere. Ohun akọkọ ti o nilo naa ni iriri rẹ pẹlu Jesu. Lẹyin eyi, o nilo igboya lati ba awọn eniyan sọrọ nipa rẹ.
Nibakan naa, bi awa naa ko tilẹ mọ ọrọ bibeli pupọ, niwọn igba ti a ba ti le sọrọ nipa iriri wa pẹlu Jesu, ti a ba ti le sọrọ nipa didara rẹ si wa, a ti ṣetan lati ṣiṣẹ ajinyinrere niyẹn. A kan nilo igboya ni lati bẹrẹ si ni pe akiyesi awọn eniyan si nkan ti Jesu ti ṣe ninu aye wa tabi ti O n ṣe ninu aye wa ki awọn naa ba le gbagbọ ninu rẹ lati ṣe ohun ara ati iyanu ninu aye ti wọn naa pẹlu. Yo si wa jẹ iyalẹnu fun wa pe laarin awọn ti a o ma ba sọrọ ni awọn ti o jẹ wipe ọkan tiwọn naa n ti n reti ẹni ti yoo dari wọn sọdọ ẹni ti o le gba aye wọn la ati fun wọn ni isinmi. Eyi jasi pe ọpọ ni o n duro de awọn ti yoo ṣe iṣẹ ajinyinrere de ọdọ wọn. Yoo si wa dara ti a ba le fi ara wa si ipo ẹni ti Ọlọrun yoo lo fun wọn.
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Ko si ẹni ti Ọlọrun ko le lo lati ṣe iṣẹ ajinyinrere, bi o ti wu ki iwa ẹni naa ma dara to. Idi si ni yi ti O fi ri arabinrin ara Samaria kan ti Jesu pade ni ilu Sikari lo fun igbala awọn ara ilu rẹ. Ti awa naa ba si wa fi ara silẹ fun lati sọ iriri wa pẹlu Jesu fun awọn ti o wa ni ayika tabi awujọ wa, o di dandan ki Ọlọrun ri awa naa lo fun igbala ọkan pupọ tabi diẹ lara wọn.
ÌBÉÈRÈ
– Ki ni awọn ẹkọ ti a ri kọ lara ọna ti Jesu gba ba arabinrin Samaria yi sọ ọrọ igbala?
– Ki ni ẹkọ ti a ri kọ lara imura arabirin Samaria yi lati polongo Jesu gẹgẹ bi Mesaya, bi ko tilẹ ti mọ daju pe Mesaya ni?
Láti ọwọ́ Johnson O. Lawal
Copyright © 2023 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07025105978)
ÀKỌ́RÍ: ṢÍṢÈ IṢẸ́ AJÍYÌNRERE – ỌMỌ Ọ̀DỌ̀ NÁMÁNÌ ÀYỌKÀ: 2ÀWỌN ỌBA 5
ÀKỌ́SÓRÍ: ”O sọ fun ọga rẹ obinrin pe, “Ti o ba jẹ wi pe ọga mi le ri wolii ti o wa ni Samaria! Yoo wo o san kuro ninu ẹtẹ rẹ.” (2Àwọn Ọba 5:3)
Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ
Ara awọn nkan ti a jẹ ki o ye wa daju ṣáká ninu bibeli ni pe Ọlọrun fẹ ki awọn ọmọ rẹ ma ṣe amulo ipokipo ti wọn ba ti ba ara wọn lati tan iyinrere didara rẹ kalẹ. Ṣugbọn ti a ko ba fi eyi si ori ọkan wa, a o ri wipe Oun ko ni le lo wa lati yi aye ẹnikẹni pada tabi lati tun aye ẹnikẹni ṣe. Ọpọ ninu wa lo si n ma gbadura tabi kọ ọ lorin pe ki Ọlọrun lo wọn fun ogo rẹ. Ko wa di igba ti Ọlọrun ti ọwọ wa ṣe iṣẹ iyanu tabi iṣẹ ara ki O to le lo wa fun ogo rẹ. Niwọn igba ti a ba duro si ipo ẹni ti o n tọ awọn miran sọna lati de ọdọ rẹ tabi lati rigba lọdọ rẹ, O ti n lo wa naa ni yẹn. O si di dandan ki O pin wa lere nigba ti asiko ba to. Eyi si ni itan ọmọ ọdọ Namani ti a fẹ gbe yẹwo ninu ẹkọ yi da le lori. Adura mi ni pe ki Ọlọrun lo itan ọdọmọdebirin yi lati ṣi oju wa si awọn nkan ti o yẹ ki a mọ nipa ṣiṣe iṣẹ ayinrere ni ibi yowu ti a ba ti ba ara wa. Amin.
TANI NAMANI?
Ki a to gbẹnu le ọrọ ọmọ ọdọ Namani ti ẹkọ yi da le lori ati ọna ti o gba ṣe iṣẹ ajinyinrere, o ṣe pataki ki a kọkọ mọ ẹni ti Namani n ṣe. Tani Namani? Bibeli dahun ibere yi nipa sisọ eyi nipa rẹ:
“Namani jẹ olori ogun ọba Aramu. O jẹ eniyan nla niwaju ọga rẹ, wọn si bu ọla fun un, nitori nipasẹ rẹ Oluwa ti fi iṣẹgun fun Aramu. Oun jẹ alagbara, akọni ọkunrin ṣugbọn, o dẹtẹ.” (2Awọn Ọba 5:1)
Ṣe o ṣe akiyesi awọn ọrọ ti a lo lati juwe ẹni ti Namani jẹ? A pe ni olori ogun ọba Aramu. A pe ni alagbara ati akọni ọkunrin. A tun ṣọ wipe o jẹ ọlọla niwaju ọga rẹ. Ki si ni idi? Idi ni pe Ọlọrun lo o pupọ lati fun orilẹ-ede Aramu ni iṣẹgun lori awọn ọta wọn. Lotitọ, ọkunrin yi ko mọ Ọlọrun – abọriṣa ni. Amọ bibeli jẹ ki o yẹ wa pe Ọlọrun ni o wa nidi aṣeyọri rẹ. A si ri ọpọ loni naa ti o gbajumọ, ti o ni ọrọ tabi ti o wa ni ipo atata ti ko si mọ wipe Ọlọrun ni O wa nidi aṣeyọri wọn. Ti iru awọn wọnyi ko ba wa ni iṣoro ti o ga ju aṣeyọri wọn lọ tabi eyi ti o sọ aṣẹyọri wọn di asan, wọn le ma gbe igbesẹ kankan lati ṣe afẹri Ọlọrun titi wọn yoo fi jade laye.
Bẹẹ gẹgẹ si ni ọrọ Namani ri. Bi o tilẹ jẹ wipe alagbara, akọni ati ọlọla eniyan ni o jẹ, adẹtẹ tun ni pẹlu. Bi a si ti ṣe mọ, adẹtẹ gbọdọ fi ilu silẹ nikẹyinkẹyin ni. Eyi wa jasi pe bi Namani ti ṣe ni ọla ati iyi ati owo to, arun ẹtẹ ti o wa ni agọ ara rẹ ko ni jẹ ki o le jẹ igbadun awọn nkan wọnyi pẹ. Bopẹ-boya, o gbọdọ fi ilu ati gbogbo awọn ti o fẹran rẹ, ti o si n wari fun silẹ lati lọ ma dagbe. Ko wa si ẹni ti o le fẹnusọ irufẹ ikoro ti arun yi fi sinu ọkunrin alagbara yi ati awọn eniyan rẹ, ki a ma tilẹ mẹnuba ti ọba rẹ.
Ṣe owo ni Namani ko ni to lati tọju ara rẹ ni? Ti oun ko ba tilẹ ni owo ti o to owo lati tọju ara rẹ, ọba rẹ n kọ? Ṣe ọba rẹ ko ni anito owo lati ran an lọwọ ni? Ọrọ owo kọ ni ọrọ ti o wa nilẹ yi. Nkan ti o ba ṣe fi owo ra ni owo le ra. Nkan ti ko ba ṣe fi owo rẹ, gbogbo owo aye yi ko le ra. Iwosan si wa lara awọn nkan ti ko ṣe fi owo ra. A le na gbogbo owo ti o wa lọwọ wa lori ilera wa. Ṣugbọn ẹni ti Ọlọrun ba wo san nikan naa ni yoo di ẹni iwosan. Ẹni ti ko ba wo san ko le di ẹni iwosan, bi o ti wu ki o nawo to lori ọrọ ara rẹ. (Wo: Maaku 5:26)
Lafikun, ṣe ko si awọn onisegun tabi alawo ti o le ran Namani lọwọ nilu ni? O di dandan ki wọn wa. Amọ, bi mo ti ṣe sọ siwaju, ẹni ti Ọlọrun funrarẹ ba wo san nikan ni o le ni ilera. Awọn oniṣegun le pa gbogbo itu ọwọ wọn, ki awọn alawo pẹlu si rubọ fun iwosan eniyan. Ti Ọlọrun ko ba ṣaanu fun un, ki O si mu larada, pabo ni akitiyan wọn yoo ja si lori rẹ.
Ẹnikẹni ti o ba ti wa sa gbogbo ipa rẹ lati yanju iṣorọ kan tabi omiran ninu aye rẹ, ti ọrọ rẹ ko si lojutu, di dandan ki o fọwọ-lẹran ma woran. Bẹẹ si ni ọrọ Namani ṣe ri ni asiko ti a n sọ yi. O ti fọwọ-lẹran lati ma wo ibi ti ọrọ ẹtẹ agọ ara rẹ yoo jasi. Ṣugbọn, Ọlọrun, Ọba Alaanu, ti o ni lọkan lati ṣaanu fun ọkunrin yi, bi ko tilẹ mọ ọn, lo ọmọdebirin kan ti o jẹ ọmọ-ọdọ labẹ iyawo rẹ lati dari rẹ lati ri iwosan ati itusilẹ gba.
Eyi si n jẹ ki o ye wa pe ko si ẹnikẹni, bi o ti wu ki ẹni naa ma ja mọ nkankan to laye yi, ti Ọlọrun ko le lo lati dari wa si ibi igbega, ayọ, itura tabi igbala ti O ti pese silẹ fun wa. Nitorina, ma ṣe foju tẹnbẹlu ẹnikẹni. Ma si ṣe ṣe igberaga si ẹnikẹni nitoripe wọn wa ni ipo irẹlẹ. Idi si ni pe iwo ko mọ ibi ti Ọlọrun ti le e lo wọn fun ọ.
TANI ỌMỌ Ọ̀DỌ̀ NÁMÁNÌ?
Ta wa ni ọmọ ọdọ Namani? A ko darukọ arabinrin yi fun wa ninu bibeli. Idi si ni pe orukọ ti eniyan n jẹ ko ni o ṣe pataki julọ ni aye yi bikoṣe nkan ti Ọlọrun ri ẹni naa lo lati ṣe. Bi a ti ṣe ri ka ninu bibeli, awọn ti Ọlọrun lo lati bẹrẹ ijọ Antioku, nibi ti a ti gbe kọkọ pe awọn ọmọ ẹyin Jesu ni Kirisitiẹni, ko ma ni orukọ ti o gbajumọ. A kan sọ wipe, “Awọn ara Saipurọsi ati Kirene kan waasu Jesu Oluwa si awọn keferi ni Antioku. Ọwọ Oluwa si wa pẹlu wọn: ọpọlọpọ eniyan si gbagbọ, wọn si yipada si Oluwa.” Nitorina, ko digba ti awọn eniyan ba mọ wa bi ẹnimowo, ki Ọlọrun to le lo wa fun ijere-ọkan ati itusilẹ awọn miran. Niwọn igba ti a ba ti jọwọ ara wa fun un, o di dandan ki O lo wa fun iṣẹ rere rẹ lalai wo ipo tabi aye ti a wa. (Wo: Iṣe Apọsiteli 11:20-21)
Bẹẹ si ni ọrọ ṣe ri pẹlu ọmọdebirin ti Ọlọrun lo fun Namani. Iwọ naa wo nkan ti a kọ silẹ nipa rẹ:
“Awọn ara Siria si ti jade lọ ni ẹgbẹẹgbẹ, wọn si mu ọmọbinrin kekere kan ni igbekun lati ilẹ Isiraẹli wa; oun si duro niwaju iyawo Naamani.” (2Àwọn Ọba 5:2)
Bawo ni ọmọ binrin kekere yi ṣe di ero ile Namani? Nipa igbekun ni! Eyi tunmọ si pe ko ki i ṣe ifẹ inu ọmọdebinrin yi ni lati wa pẹlu Namani tabi iyawo rẹ. Nṣe ni a mu ni igbekun wa si ile wọn. O tilẹ wa ṣeeṣe ki a ti pa awọn obi rẹ ni asiko ti a mu gẹgẹ bi ẹru wa si orilẹ-ede Aramu. Eyi n jẹ ki o ye wa pe oju ọta ati ika eniyan ni o yẹ ki ọmọ yi ma a fi wo Namani, aya rẹ ati gbogbo awọn ara Aramu. Ti o ba si wa ni oore-ọfẹ lati ṣe wọn ni ijamba, nṣe ni o yẹ ki o yara kankan lati ṣe amulo rẹ.
Iyalẹnu ni o wa jẹ pe ọmọ yi ko fi aye silẹ ninu ọkan rẹ fun ẹtanu tabi ikoro rara, bi o tilẹ jẹ wipe ipo ẹru ni o wa. Nṣe ni o gbọnranu, ti o si gbajumọ igbe aye rẹ tuntun ati awọn nkan ti o sorọ mọ. Eyi si ni o fun ni anfaani lati wa ni ipo ẹni ti o le ba iyawo ọga rẹ sọrọ. Ọpọ ni ko le ba awọn ti o jẹ ọga wọn nibi iṣẹ, awọn ọmọ iṣẹ wọn tabi awọn ti o wa ni awujọ wọn sọrọ Jesu nitoripe iwa ati iṣesi wọn ko suwọn.
Ṣugbọn ọdọmọdebirin iranṣẹ aya Namani yi ko ri bayẹn rara. Iwa rẹ, iṣeṣi rẹ, wu awọn oluwa rẹ lori tobẹ ẹ gẹẹ ti wọn fi fi aye silẹ fun wọn lati le ba wọn sọ awọn ọrọ ti o ni i ṣe pẹlu aye wọn. Ọrọ rẹ wa dabi ọrọ Josefu ni oko ẹru Ijibiti. Bi o tilẹ jẹ wipe ko ki i ṣe ifẹ inu rẹ ni lati wa ni ipo ẹru, ko jẹ ki eyi pa ijafafa ati erongba rẹ lati di ẹni nla lara. Nitorina, o gbajumọ iṣẹ rẹ, o si di ẹni ti o tayọ laarin awọn ẹru yoku. Eyi ni o jẹ ki o di alakoso ile ati ohun ini oluwa rẹ. Nigba ti o si tun ba ara rẹ ni ọgba ẹwọn pẹlu, fun ẹsun aimọdi, ko fi aye gba irẹwẹsi ọkan rara. Nṣe ni o fi ara rẹ han bi ẹni ti o ṣe fi ọkan tan. Eyi si tun jẹ ki o di aṣoju alakoso ọgba ẹwọn naa. Ipo yi ni o wa ti Ọlọrun fi da a lare, ti O si gbe ori rẹ soke. (Wo: Jẹnẹsisi 39-41)
Nitorina, ohun yowu ti o gbe o de ibi ti o wa ko jamọ nkankan. Nkan ti o ṣe pataki ni ohun ti o fi asiko rẹ nibi yowu ti o ba wa ṣe. Ọdọmọdebirin ti a sọ di ẹru nile Namani yi ko jẹ ki ipo ti o wa sọ di ọdaran, ẹlẹtanu tabi ika eniyan. Dipo bẹ, nṣe ni o lo ipo naa lọna ti o fi di ẹni ti o ri ojurere aya oluwa rẹ. Ti iwọ naa ba si lo ipo ti o wa ni ọna ti o tọ, o di dandan ki Ọlọrun jẹ ki o ba aanu ati ojurere pade lati di ẹni igbega ati ẹni ayẹsi.
IṢẸ́ ÀJÍYÌNRERE
Wayi o, bi o tilẹ jẹ wipe ipo ẹru ni ọmọdebirin ti a n sọrọ rẹ yi wa ni ile Namani, oun naa ma ni iwulo tirẹ. Pe eniyan jẹ ẹru tabi talaka tabi ẹni ti ko kawe ko ma tunmọ si pe ko le wulo fun wa rara. Awọn nkan wa ti ẹru, talaka tabi ẹni ti ko le fi idi igo ko odo le mọ ti awa ti a kawe, lọrọ tabi gbajumọ le ma mọ. Awọn nkan wọnyi si le sọ wa di ope tabi alaimọọṣe ni awọn abala aye wa kan.
Namani ati iyawo rẹ ni ọrọ, wọn gbajumọ, wọn si tun lagbara. Sibẹsibẹ, wọn ko ma mọ ọna si ilera ọkunrin yi. Wọn ko mọ ibi ti wọn le ti ri iwosan fun. Ṣugbọn ọdọmọdebirin ẹru ti o wa ni ọdọ wọn yi mọ ọn. Yatọ si pe o mọ ọn, o tun la ẹnu rẹ lati sọ fun wọn. Ki lo fa? O jẹ ẹni ti o ni oju aanu. O si tun jẹ ẹni ti ko ki i fi buburu san buburu.
Ẹni ti ko ba ni oju aanu ko le ran awọn ti o ba wa ninu ipọnju lọwọ. Idi si ni pe ko le ri ti wọn ro. Ẹni ti o ba si kun fun ẹtanu tabi arankan ko le ran awọn ti o wa ninu iponju lọwọ. Nitoripe bi wọn yoo ti ṣe jẹ iya ẹṣẹ ti wọn ṣẹ si lẹkunrẹrẹ ni yoo wa lọkan rẹ. Nitorina, ti o ba tilẹ mọ ọna ti wọn fi le gba ni itura tabi igbala, ko ni i sọ fun wọn. Ọlọrun ko si le lo irufẹ awọn wọnyi lati ṣiṣẹ ajinyinrere tabi ijere-ọkan.
Yatọ si awọn nkan ti a ti sọ nipa ọmọdebirin yi, o tun jẹ ọmọ ti oye ye pe ibi ti ẹniyan ba n gbe, ti o n ti n jẹ, ti o si ti n mu, nṣe ni o yẹ ki o tun ibẹ ṣe – nṣe ni o yẹ ki o ma wa alaafia ibẹ dipo iparun ibẹ. Oye yi kanna ni Ọlọrun si fẹ ki awọn eniyan rẹ ti o ba ara wọn igbekun ni akoko Wolii Jeremaya ni. O fẹ ki wọn mọ pe wọn nilo lati ma gbadura fun ilẹ awọn ti o ko wọn ni igbekun, ki wọn si ma wa alaafia ati ilọsiwaju wọn. Idi si ni pe alaafia ati ilọsiwaju ti awọn funralara wọn sorọ mọ. (Wo: Jeremaya 29:4-7)
Ni kukuru, nitori pe ọmọdebirin yi jẹ alaanu ati ẹni ti o n wa alaafia fun ile oluwa rẹ, o bẹrẹ si ni tẹ mọ aya rẹ leti pe ti oluwa oun ba lọ ri wolii Ọlọrun ti o wa ni Samaria, ẹtẹ rẹ yoo san. Iwọ naa wo nkan ti a kọ silẹ lori eyi:
“O sọ fun ọga rẹ obinrin pe, “Ti o ba jẹ wi pe ọga mi le ri wolii ti o wa ni Samaria! Yoo wo o san kuro ninu ẹtẹ rẹ.” (2Awọn Ọba 5:2)
Ṣe a wa kọbiara si ọrọ ọdọmọdebirin yi bi tabi a ko kọbiara si? A ma kọbiara si i. Wo nkan ti a sọ nipa rẹ:
“Namani lọ si ọdọ ọga rẹ o si wi fun un ohun ti ọmọbinrin Isirẹli ti sọ. “Ni gbogbo ọna, lọ,” ọba Aramu da a lohun pe, “Emi yoo fi iwe iranṣẹ si ọba Isirẹli.” Bẹẹ ni Namani lọ, o si mu pẹlu rẹ talẹnti fadaka mẹwaa, ẹgbẹta iwọn wura (6,000) ati iparọ aṣọ mẹwaa. Iwe ti o mu lọ sọdọ ọba Isirẹli ka pe: “Pẹlu iwe yii emi n ran iranṣẹ mi Namani si ọ pe o le wo o san kuro ninu ẹtẹ rẹ.” (2Awọn Ọba 5:4-5)
Ki lo fa ti Namani fi gbe ọrọ ti ọmọ ọdọ rẹ yi sọ fun lori ọna lati ri iwosan lọ siwaju oluwa rẹ, iyẹn ọba Aramu? Idi ni pe ọmọ yi ko dẹkun lati ma sọrọ lori rẹ ati lati ma fi ọwọ sọya fun pe ti o ba lọ si ibi ti oun fẹ ki o lọ, o di dandan ki o ri iwosan. Ṣe o wa ri iwosan tabi ko ri? O ma ri kẹ. Ọlọrun ma wosan patapata. Ọlọrun wo o san nitoripe ẹnikan n fi gbogbo igba tẹnumọ fun pe Ọlọrun le e ṣe.
Ki ni eleyi n kọ wa? Akọkọ, o n kọ wa pe ti awa ti a ti jẹgbadun didara Oluwa ba fẹ ki O ti ipasẹ wa fi didara rẹ han si awọn miran, a gbọdọ ni aanu awọn ti ko mọ ọn loju, a ko si gbọdọ fi aye gba ẹtanu tabi arankan ni ọkan wa. Ekeji, ti a ba fẹ ki awọn eniyan tọ Jesu wa nitootọ fun igbala ọkan wọn tabi itusilẹ wọn kuro lọwọ eṣu, a gbọdọ ba wọn sọrọ pẹlu idaniloju pe Ọlọrun le mojuto ọrọ aye wọn. Aijẹbẹ, wọn ko ni mu ọrọ wa ni pataki debi wipe wọn yoo gbe igbesẹ le lori. Ẹkẹta, bi a ti ṣe sọ tẹlẹ, iwuwasi ati iṣesi wa ni ipa ti o ga lati ko lori boya a o ni anfani lati ba awọn eniyan sọrọ nipa igbala ati itusilẹ ti o wa ninu Jesu tabi a ko ni ni i. Ti iwa wa ba suwọn, o ṣeeṣe ki awọn eniyan titori rẹ fun wa ni aaye lati ba wọn sọrọ igbala ọkan ati aye wọn. Ṣugbọn ti iwa wa ko ba suwọn, Ọlọrun le ma le ri wa lo fun igbala atabi itusilẹ wọn.
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Ko si ẹni ti Ọlọrun ko le lo lati ṣe iṣẹ ajinyinrere tabi ijere-ọkan niwọn igba ti o ba ti rẹ ara rẹ silẹ, ti ko si fi aye gba ipo yowu ti o wa lati di lọwọ lati ba awọn ti o wa ninu iyọnu sọrọ nipa agbara Ọlọrun lati tu wọn silẹ. Nitorina, ipo yowu ti o ba wa, bi o tilẹ jẹ ipo ọmọ ọdọ tabi ti iranṣẹ, niwọn igba ti o ba ti mọ Ọlọrun, ri mọ daju pe o fi aaye silẹ fun un lati le lo ọ ni ipo naa lati tun aye ọpọ ṣe. Amọ eyi ko ni waye ti iwa rẹ ko ba suwọn, ti o ko si mu iṣẹ rẹ ni ọkunkundun ati pẹlu ọyaya, ki o si jẹ ki awọn ti o wa ni ayika rẹ mọ pe ipo rẹ laye yi ko yi ipo rẹ ninu ijọba Ọlọrun pada.
IBEERE
– Sọ nkan mẹta pataki ti o kọ ninu ẹkọ yi
Láti ọwọ́ Johnson O. Lawal
Copyright © 2023 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07025105978)
ÀKỌ́RÍ: ADÈNÀ ÀDÚRÀ ÀYỌKÀ: 1PÉTÉRÙ 3:7
ÀKỌ́SÓRÍ: ”Bẹẹ gẹgẹ ẹnyin ọkọ, ẹ maa fi oye ba awọn aya yin gbe, ẹ maa fi ọla fun aya, bi ohun elo ti ko lagbara, ati pẹlu bi ajumọjogun oore-ọfẹ iye; ki adura yin ma ba a ni idena.“ (1Pétérù 3:7)
Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ
Ara awọn nkan ti Bibeli fi ye wa ni pe Ọlọrun ko ki i lọra rara lati dahun adura awọn ọmọ rẹ. Dipo eyi, ni kete ti wọn ba ti gbadura si naa ni O ma n dawọn lohun. A si ri oniruuru apẹrẹ ti o fi idi eyi mulẹ ninu bibeli. Sibẹsibẹ, a tun ri ninu bibeli yi kanna pe o ṣeeṣe ki awọn eniyan gbadura ki Ọlọrun ma gbọ debi pe yoo da wọn lohun. Ki wa lo ma n fa eyi? Ṣe Satani ati awọn ọmọ ogun rẹ lo n fa a? Ṣe awọn ajẹ tabi awọn emere tabi awọn oṣo ni o n fa a? Tabi ṣe awọn eniyan funra wọn ni o n fa a? Awọn ibere ti a fe dahun ninu ẹkọ yi ti o da lori ‘Adena adura’ niyẹn. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun ohun gbogbo ti a o gbe yẹwo ninu ẹkọ naa lati fi imọ ati oye kun imọ ati oye ti o ti ni tẹlẹ lori adura gbigba, ki o ba le pọ si ni isesorere gẹgẹ bi aladura.
ADÈNÀ ÀDÚRÀ
Bi mo ti ṣe sọ siwaju, bibeli fi ye wa yekeyeke wipe Ọlọrun ma n dahun adura awọn ti o ba kepe lalai fi asiko ṣofo. Fun apẹẹrẹ, Jesu, nigba ti O n kọ awọn ọmọ ẹyin rẹ lati ma gbadura laisimi ati laiṣaarẹ sọ eyi fun wọn: “Ọlọrun ki yoo ha si gbẹsan fun awọn ayanfẹ rẹ ti n fi ọsan ati oru kigbe pe e, ti o si mu suuru fun wọn. Mo wi fun yin, yoo gbẹsan wọn kankan…” (Luuku 18:7-8) Eyi n fi han wa pe Ọlọrun ko ki i fi ọrọ awọn eniyan rẹ ti o n gbadura si falẹ rara. Ni kankan ni o ma n da wọn lohun.
Fun apejuwe, nigba ti iranṣẹ Aburahamu ti o ran lati wa aya fun Isaaki ọmọ rẹ de ilu ti a ran an si, o gbadura si Ọlọrun ki o ṣe ọna rẹ ni rere. Bibeli si wa sọ eyi nipa adura naa ti o gba: “Ki o to di pe, o pari adura, Rebeka de pẹlu ikoko omi rẹ ni ejika rẹ…” (Jẹnẹsisi 24:15) Eyi ja si pe ki ọkunrin yi too gbadura rara ni Ọlọrun ti pese ọmọbinrin ti yoo jẹ idahun si adura rẹ silẹ. Ọlọrun tilẹ ti ran ọmọ naa jade si. Amọ adura ti o gba ni o ran an lọwọ lati ṣe idamọ ẹni ti o tọ fun Isaaki gẹgẹ bi aya.
Si wa ranti pe Jesu sọ fun wa pe Ọlọrun ti mọ gbogbo aini wa ki a to bere ohunkohun lọwọ rẹ (Matiu 6:8&32). Iyẹn jasi pe ko si adura ti a fẹ gba si Ọlọrun ti yoo ja si iyalẹnu fun. Ohun gbogbo ti a nilo ati ti a le bere lọwọ rẹ ni O mọ, ti O si ti pese silẹ fun wa. Adura wa kan jẹ ọkan lara ọna fun wa lati fi igbagbọ wa ninu rẹ han ati lati ṣe idamọ awọn ipese rẹ fun wa.
A tun ri apẹrẹ miran lati ara Samusoni. Ọjọ kan wa, bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ti ongbẹ fẹ pa ọkunrin yi lẹyin ti o ti jagun-ṣẹgun tan. O wa gbadura si Ọlọrun lọna ti a gba kọ ọ silẹ yi:
“Nitori ti ongbẹ gbẹ ẹ gidigidi, o ke pe Oluwa, wi pe, “Iwọ ti fun iranṣẹ ni iṣẹgun ti o tobi yii. Ṣe emi yoo ha ku pẹlu ongbẹ, ki emi si ṣubu si ọwọ awọn alaikọla eniyan?” Nigba naa ni Ọlọrun la koto isun omi ti o wa ni Lehi, omi si tu jade lati inu rẹ. Nigba ti Samusoni mu mi tan, agbara rẹ si pada, ọkan si sọji, fun idi eyi wọn pe isun omi naa ni. Ẹni Hakkore (orisun ẹni ti o pe Ọlọrun) eyi ti o si wa ni Lehi di oni.” (Onidajọ 15:18-19)
Ki ni ẹkọ ti a ri kọ nibi yi? Akọkọ ni pe Ọlọrun a ma dahun awọn ti o ba kepe ni kiakia, lẹsẹkẹsẹ. Ni kete ti Samusoni kepe Ọlọrun fun omi ni O da lohun – ko fi falẹ rara. Ẹkọ ekeji ti a ri kọ ni pe ipese Ọlọrun ti wa nilẹ fun Samusoni ki o to di asiko ti o gbadura yi. Orisun omi ti wa ni ibi ti ọkunrin yi ti gbe gbadura lọjọ yi ki o to di pe o de ibẹ gbadura. Ṣugbọn nigba ti o gbadura tan, Ọlọrun ṣi ilẹ fun isun omi naa lati tu jade. Lati igba naa lọ ni awọn eniyan si ti bẹrẹ si ni jẹ igbadun rẹ.
A tun ri apẹrẹ miran lara Daniẹli ati bi o ti ṣe gba idahun si adura ti o gba si Ọlọrun ni asiko kan. Iwọ naa wo awọn ẹṣẹ bibeli yi ti o sọrọ nipa rẹ:
“Nigba naa, ni mo yipada si Oluwa Ọlọrun, mo bẹẹ pẹlu adura ati ẹbẹ, pẹlu aawẹ, aṣọ ọfọ ati eeru.” (Daniẹli 9:9)
“Bi mo ṣe n gba adura naa lọwọ, Geburẹli ọkunrin ti mo ri ninu iran iṣaaju, yara kankan wa si ọdọ mi ni akoko ẹbọ aṣaalẹ. O jẹ ki o ye mi, o si wi fun mi pe, Daniẹli, mo wa lati jẹ ki o mọ ki o si ni oye. Bi o ṣe bẹrẹ si ni gba adura, a fun ọ ni idahun kan, eyi ti mo wa lati sọ fun ọ, nitori iwọ jẹ ayanfẹ gidigidi. Nitori naa, gba ọrọ naa yẹwo ki iran naa si ye o…” (Daniẹli 9:21-23)
Ṣe o ri bayi pe lọwọlọwọ ti Daniẹli n gbadura si Ọlọrun naa ni O da lohun, ti O si ran angẹli rẹ kan si lati fun ni idahun si adura rẹ. Ti o ba kiyesi akọsilẹ yi daradara, iwọ naa yoo ri pe Daniẹli sọ wi pe ni KÀNKÀN ni angẹli naa wa si ọdọ rẹ lati fun ni idahun si adura rẹ. Eyi n jẹ ki o ye wa pe Ọlọrun ko ki i lọra rara lati dahun adura awọn eniyan rẹ. Ti a ba si ni ki a tẹsiwaju lati wo apẹrẹ melokan miran si ninu bibeli, a ko ni ri aye wo koko ẹkọ wa mọ.
Wayi, a le wa ma bere idi ti a ko i ti fi ri idahun si awọn adura kan ti a n ti n gba fun ọjọ melokan sẹyin tabi fun ọjọ pipẹ. Nkan mẹta ni o le e fa a. Akọkọ, o ṣeeṣe ki o jẹ wipe awọn nkan ti Ọlọrun nilo lati ṣe ki idahun si ibere wa to tẹ wa lọwọ ṣe diẹ tabi yo gba akoko diẹ. Ẹ ma si gbagbe pe awa ni oju ma n kan. Oju ko ki i kan Ọlọrun. Nitorina, bi a tilẹ ro wipe ọjọ n lọ lori awọn ọrọ aye wa kan, Ọlọrun le ma ri bi igba ti ọjọ n lọ rara.
Fun apẹrẹ, lati pese olugbala ti o koju oṣuwọn fun awọn ọmọ Isiraẹli ti o n kegbe si Ọlọrun fun itusilẹ wọn kuro ni oko ẹru Ijibiti, o gba Ọlọrun ni o kere ju ọgọrin ọdun. O ṣeeṣe ki Ọlọrun ma fẹ ki o to bẹ ẹ. Ṣugbọn igba ti Mose to ṣetan naa ni Ọlọrun to ran an lati gba awọn eniyan rẹ la, eyi si wa jasi ọgọrin ọdun. Ki wa ni ki a sọ nipa awọn adura ti awọn ọmọ Iṣiraẹli ba n gba si Ọlọrun ni asiko ti O n pese Mose silẹ fun wọn yi? Ṣe ki a sọ wipe ko dahun wọn ni? O dahun wọn. Amọ, ki idahun naa to fi ara han, o gba a ni o kere ju ọgọrin ọdun.
Ki a tun wo igba ti Mose kigbe pe Ọlọrun lati gba awọn ọmọ Isiraẹli la kuro lọwọ ogun Ijibiti ti o ṣe wọn mọ bebe okun pupa. Ṣe Ọlọrun da lohun ni kiakia tabi ko da lohun? O da lohun. O sọ fun pe ki o na ọpa ọwọ rẹ sori okun pupa lati pin in niya. Amọ ṣe ni ẹsẹkẹsẹ naa ni okun yi pin si meji? Rara o! Bibeli sọ wipe, “Nigba naa ni Mose na ọwọ rẹ si ori okun, ni gbogbo oru naa ni Oluwa fi le okun sẹyin pẹlu iji lile lati ila-oorun wa, o si sọ ọ di iyangbẹ ilẹ. Omi okun si pinya.” (Ẹ́kísódù 14:21-22) Ṣe o ri bayi? Odidi oru ọjọ kan ni o gba iji-lile ti Ọlọrun ran lati pin okun pupa niya lati pari iṣẹ rẹ. Nitorina, pe a ko i ti ri ifarahan idahun si adura wa ko tunmọ si pe Ọlọrun ko da wa lohun. O ṣeeṣe ki o je wipe idahun naa ti wa ni oju ọna. Ti a ko ba si rẹwẹsi ninu igbagbọ wa ninu Ọlọrun, o di dandan ki idahun naa tẹ wa lọwọ.
Nkan ekeji ti o le fa ki a ma tete ri ifaharan idahun si adura wa ni idena Satani. Njẹ Satani tabi awọn ọmọ ogun rẹ le dena adura wa, ki o ma se de eti Ọlọrun? Rara, Satani ati awọn ọmọ ogun rẹ ko le dena adura wa ki o ma de ọdọ Ọlọrun. Bẹẹ ṣi ni wọn ko le di Ọlọrun lọwọ lati da wa lohun. Lotitọ, olufisun ni Satani. Nitorina, gẹgẹ bi o ti ṣe si Jobu ati si Joṣua olori alufa ninu we mimọ ni o ma n fẹ ṣe si gbogbo eniyan. Eyi tunmọ si wipe Satani le sọ wipe ko tọ fun Ọlọrun lati fun wa ni awọn nkankan ti a n bere lọwọ rẹ, yala nitori ẹṣẹ wa tabi aiṣedede wa. O si tun le sọ fun Ọlọrun pe ki o ma fun wa ni awọn nkankan lati dan igbagbọ wa ati lati ri pe ko munadoko. (Wo: Jóòbù 1-2; Sẹkaráyà 3:1-5; Lúùkù 22:31-32; Ìfihàn 12:10-12)
Amọ bibeli jẹ ki o ye wa pe a ni alagbawi kan lọdọ Baba wa, iyẹn Jesu Kirisiti ti O ku fun ẹṣẹ wa ati ti gbogbo araye. Alagbawi yi ni O si ma n fi gbogbo igba jẹri pe Oun ti ku fun ẹṣẹ wa. Nitorina, Ọlọrun ko nilo lati wo ẹṣẹ ti a ti san gbese rẹ gẹgẹ bi idi lati ma da wa lohun. Ara idi niyi ti a ṣe kilọ fun wa lati ma bo ẹṣẹ wa mọlẹ ṣugbọn ki a jẹwọ rẹ. Aijẹbẹ, a o fun Satani ni anfaani lati wa ẹṣun si wa lọrun niwaju Ọlọrun. (Wo: Róómù 8:34; Hébérù 7:25; 1Jòhánù 2:1-2)
Lọrọkan ṣa, nkan ti a n sọ nipe bi o tilẹ je wipe Satani ko le di adura wa lọwọ lati de eti Ọlọrun, o le gbiyanju lati ma jẹ ki idahun rẹ tete tẹ wa lọwọ tabi tẹ wa lọwọ rara. Ti o ba gbiyanju lati wa ẹsun si wa lọrun niwaju Ọlọrun ti ko si ṣeeṣe, o le bẹrẹ si ni ṣe oniruuru nkan lati ri pe idahun si adura wa ko de ọdọ wa rara tabi ki o pẹ de ọdọ wa. Ara idi si niyi ti Jesu fi sọ wipe o yẹ ki awọn eniyan ma gbadura lalai ṣaarẹ (Luuku 18:1).
Fun apẹrẹ, a ri igba kan ti Daniẹli gbadura si Ọlọrun lati fi oye iran kan han an fun ọjọ mọkanlelogun ki o to ri idahun si adura yi gba. Ṣugbọn ẹ wo nkan ti angẹli ti o mu idahun naa wa sọ fun:
“Ma ṣe bẹru Daniẹli. Lati ijọ akọkọ ti iwọ ti fi ọkan rẹ silẹ niwaju Ọlọrun rẹ, a gbọ ọrọ rẹ, mo si wa nitori ọrọ naa. Ṣugbọn ọmọ alade ijọba Pasia da mi duro fun ọjọmọkanlelogun. Nigba naa ni Maikẹli, ọkan lara ijoye awọn ọmọ alade, wa lati ran mi lọwọ, nitori a da mi duro nibẹ pẹlu ọba Pasia.” (Dáníẹ́lì 10:12-13)
Ṣe o ri bayi? Ọjọ ti Daniẹli ti gbadura ni Ọlọrun ti da lohun, ti O si ti ran angẹli rẹ kan lati mu idahun naa wa fun. Ṣugbọn ẹmi buburu ti o n ṣakoso ijọba Pasia ni asiko yi ko jẹ ki o de ọdọ Daniẹli. Afi igba ti Ọlọrun to ran angẹli miran lati lọ tu silẹ kuro lọwọ rẹ ni o to raye de ọdọ Daniẹli. Ti Daniẹli ba ti wa rẹwẹsi ninu adura gbigba nkọ? O ṣeeṣe ki o ma lailai gburo esi adura naa.
Nitorina, ara, ma ṣe rẹwẹsi ninu adura gbigba rara, bi o ti wu ki nkan le to. O seese ki Ọlọrun nilo lati ṣe oniruuru iyanu, bi O ti ṣe ṣe lati yọ Isiraẹli kuro ni oko ẹru, ki O to le ri ifarahan idahun si adura rẹ. Ti iwọ ko ba si rẹwẹsi, o di dandan ki nkan ti o n fẹ ki o tẹ ọ lọwọ.
Nkan ẹkẹta ti o le fa ki a ma ri ifarahan idahun adura wa ni ki Ọlọrun ma dahun rara. Ṣe o ṣeeṣe ki a gbadura si Ọlọrun ki O si ma dahun? Bẹẹni, o ṣeeṣe. Bibeli jẹ ki o ye wa pe o ṣeeṣe ki a gbadura si Ọlọrun ki o si ma gbọ tabi dahun. Eyi tunmọ si pe Satani kọ ni o n dena adura wa ni asiko yi; awa tikarawa ni a n dena rẹ. Ki wa ni o le e fa? Ki ni o le sọ wa di oludena adura ara wa? Awọn nkan mẹta yi ni a jẹ ki o ye wa pe o le fa a.
– Iyèméjì: Jemiisi, ninu lẹta rẹ, sọ eyi fun wa: “Bi o ba ku ọgbọn fun ẹnikẹni, ki o beere lọwọ Ọlọrun ẹni ti fi fun gbogbo eniyan ni ọpọlọpọ, ti ki i ṣi ka alebu si, a o si fi fun un. Ṣugbọn nigba ti oun ba beere ni igbagbọ, ni aiṣiyemeji rara. Nitori ẹni ti o n ṣe iye meji dabi igbi omi okun, ti a n ti ọwọ afẹfẹ bi siwa bi ṣẹyin, ti a si n ru u soke. Ki iru ẹniyan bẹẹ ma ṣe ro pe, oun yoo ri ohunkohun gba lọwọ Oluwa. O jẹ eniyan oniyemeji alaileduro ni ọna rẹ gbogbo.” (Jakọbu 1:5-8) Kini Jemiisi fẹ ki o ye wa pẹlu awọn nkan ti o sọ yi? Oun naa ni pe ti a ko ba pa ọkan wa pọ lati ri nkan ti a fẹ gba lọwọ Ọlọrun gba, Ọlọrun ko ni dawa lohun. Fun apẹẹrẹ, a ri awọn ti wọn ma n gbadura si Ọlọrun ṣugbọn ti wọn si tun ni awọn etekete kan lọkan ti wọn fẹ tẹle lati yanju iṣoro wọn tabi ti wọn si tun ma n tọ awọn alawo tabi oniṣegun tabi awọn alufa ti ko mọ Ọlọrun lọ. Irufẹ awọn wọnyi ko le ri nkankan gba ni ọwọ Ọlọrun nipasẹ adura wọn. Idi si ni pe awọn ti o ba ni ọkan pipe si Ọlọrun nikan ni o le ri nkan gba lọwọ rẹ nipasẹ adura (2Kiróníkà 16:9). Ti iwọ naa ko ba wa fẹ jẹ adena fun adura ara rẹ, yoo san ki o fi gbogbo ọkan rẹ tan Ọlọrun, ki o fi gbogbo igbagbọ rẹ sinu rẹ. (Wo: 1Sámúẹ́lì 28:3-25)
– Gbígbàdúrà lòdì sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: Johanu sọ eyi fun wa nipa gbigbadura lati rigba lọwọ Ọlọrun: “Eyi si ni igboya ti awa ni niwaju rẹ, pe bi awa ba beere ohunkohun gẹgẹ bi ifẹ rẹ, o n gbọ ti wa; Bi awa ba si mọ pe o n gbọ ti wa, ohunkohun ti awa ba beere, awa mọ pe awa ri ibeere ti awa ti beere lọdọ rẹ gba.” (1Johanu 5:14-15) Ki ni yoo jẹ ki Ọlọrun gbọ ti wa ti a ba gbadura si? Ki a gbadura ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ ni. Bawo ni a wa ṣe le mọ ifẹ rẹ? Ọna kan gboogi lati mọ ifẹ rẹ ni nipa kika iwe mimọ ati ṣiṣe aṣaro ninu rẹ. O wa seni laanu pe ọpọ ti o pe ara wọn ni ọmọ Ọlọrun, ti wọn si ni bibeli lọwọ, ni o ma n mọọmọ kọ aṣẹ Ọlọrun lori adura gbigba silẹ lati ṣe ifẹ inu ara wọn. Fun apẹrẹ, Jesu sọ eyi nipa adura gbigba: “Ṣugbọn nigba ti ẹyin ba n gbadura, ẹ ma ṣe atunwi asan bi awọn keferi; wọn ṣebi a o titori ọrọ pupọ gbọ ti wọn. Nitori naa ki ẹyin ma ṣe dabi wọn. Baba yin saa mọ ohun ti ẹyin ṣe alaini ki ẹ to beere lọwọ rẹ.” (Mátíù 6:7-8) Ẹnikẹni ti o ba wa n gbadura ti ko si tẹle ilana yi n gbadura lodi si ifẹ Ọlọrun. Nitorina Ọlọrun ko le gbọ tabi dahun. Eyi ko tunmọ si pe Ọlọrun ko ni ṣe ohunkohun fun ẹni yi. Alaanu ni Ọlọrun. Nitorina, ko di igba ti a ba gbadura si ki O to ṣe nkan fun wa. A wa gbọdọ mọ wipe ko ki i ṣe gbogbo nkan ti Ọlọrun ba ṣe fun wa naa ni O ṣe nitori adura wa. Ọpọ nkan ni O n ṣe fun wa nigba ti a ko gbadura rara, gbadura to tabi gba agbadanu adura. Nitori eyi, ti o ba n jẹ igbadun Ọlọrun, bi o tilẹ jẹ wipe o n gba ọpọ adura lodi si ifẹ rẹ, ma ro wipe nitori ti o mọ adura gba ni o ṣe n jẹ igbadun rẹ. Rara o. Nitori aanu rẹ ni o ṣe n jẹ igbadun rẹ. Ti o ko ba si ronupiwada, ọpọlọpọ nkan ni o o ma padanu rẹ, bi a tilẹ mọ ọ si afadurajagun.
– Ẹ̀ṣẹ̀: Bi mo ti ṣe sọ siwaju, Jesu ti san gbese gbogbo ẹṣẹ wa ati ti gbogbo araye (1Jòhánù 2:1-2). Amọ ṣa, ti a ba n gbe ninu ẹṣẹ, ti a si kọ lati gba nkan ti Ọlọrun n sọ fun wa nipa ẹṣẹ wa, ki a ba le gba idariji, ko si ni ki eyi ma ṣe idena fun adura wa ni ọna kan tabi omiran. Ti a ba wa n ṣọrọ nipa idena ẹṣẹ fun adura, ko ki i ṣe kiki ẹṣẹ bi agbere, ole jija tabi iṣẹṣo nikan ni o le dena adura wa. Ohunkohun ti o ba lodi si ifẹ Ọlọrun ti a n ṣe ni o le dena adura wa, ki Ọlọrun ma ṣe gbọ ọ depo pe yoo dahun rẹ. Eyi jasi pe awọn ẹṣẹ bi ojukokoro, igberaga, ẹtanu, ilara, rikisi, iṣọtẹ, agabagebe, aidariji awọn ti o ṣẹ wa ati bẹẹbẹẹ lọ ni o le dena adura wa. Ki a ma yan awọn ti o wa ni abẹ wa jẹ gan le dena adura wa. Ki a si ma fi ifẹ ati otitọ ba awọn ti o wa ninu aye wa tabi idile wa lo naa le dena adura wa. Fun apẹrẹ, Peteru sọ eyi fun awọn ọkunrin ijọ: ”Bẹẹ gẹgẹ ẹnyin ọkọ, ẹ maa fi oye ba awọn aya yin gbe, ẹ maa fi ọla fun aya, bi ohun elo ti ko lagbara, ati pẹlu bi ajumọjogun oore-ọfẹ iye; ki adura yin ma ba a ni idena.“ (1Pétérù 3:7) Ṣe o ri bayi? Ti o ko ba ṣe daradara si ẹnikeji rẹ ninu igbeyawo rẹ, yala aya rẹ ni tabi ọkọ rẹ, o ṣeeṣe ki o dena awọn adura kan ti o n gba si Ọlọrun. Ewo gan wa ni yoo dena? Ko si ẹni ti o le sọ. Idi niyi ti o ṣe gbọdọ mura lati ma ṣe gbogbo ifẹ Ọlọrun fun ọ, bi a ti ṣe la a kalẹ ninu iwe mimọ. Aijẹbẹ, o ni mọ ibi ti o o ti fi aye silẹ fun idena adura rẹ. (Wo: Àìsáyà 59:1-2)
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Ọlọrun ko ki ṣe Ọlọrun ti o ma n fi ọrọ awọn eniyan rẹ jafara tabi ṣere. Nitorina, ni kete ti wọn ba ti gbadura si ni O ma n da wọn lohun. Amọ ti oye awọn nkan ti o le dena adura wọn tabi ifarahan idahun si adura wọn ko ba ye wọn, o ṣeeṣe ki wọn rẹwẹsi ninu adura gbigba.
ÌBÉÈRÈ
– Sọ nkan mẹta pataki ti o kọ ninu ẹjọ yi.
Láti ọwọ́ Johnson O. Lawal
Copyright © 2023 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07025105978)
ÀKỌ́RÍ: KÍ NI Ẹ̀RÍ RẸ LÁÀRIN WỌN | ÀYỌKÀ: 3JÒHÁNÙ 1-14 | ỌJỌ́RÚ 08, ẸRẸ́NÀ 2023
ÀKỌ́SÓRÍ: “Olufẹ, ma ṣe afarawe ohun ti i ṣe ibi bi ko ṣe ohun ti ṣe rere. Ẹni ti o ba n ṣe rere ti Ọlọrun ni; ẹni ti o ba n ṣe buburu ko ri Ọlọrun.” (3Johanu 11)
Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ
Niwọn igba ti a ba n gbe inu aye yi, awọn eniyan ko le ṣe kan ma sọrọ nipa wa. Wọn n sọrọ nipa awọn ti o ti ku gan – ki a ma wa sọ ti awọn ti o si wa laaye. Amọ irufẹ nkan wo ni wọn n sọ nipa wa? Bawo si ni nkan ti wọn n sọ nipa wa ṣe jẹ otitọ si? Gẹgẹ bi a ti ṣe ri ninu bibeli, Ọlọrun ko fẹ ki a gbe ara le nkan ti awọn eniyan ba n sọ nipa wa, yala rere ni tabi buburu. Dipo eyi, nkan ti O ba sọ ninu ọrọ rẹ nipa wa ni O fẹ ki a gbe ara le, ki a mu ni pataki, ki a si jẹ ki o ma ṣe atọna bi a ti ṣe n gbe aye wa. Eyi ko wa jasi pe ko fẹ ki a bikita rara nipa nkan ti awọn eniyan n sọ nipa wa. O fẹ ki a bikita nipa rẹ niwọn bi yoo ti ṣe pa nkan ti wọn yoo ma ti ipasẹ wa sọ nipa rẹ lara. Idi niyi ti Jesu fi sọ wipe, “Bakan naa, ẹ jẹ ki imọlẹ yin ki o mọlẹ niwaju eniyan to bẹẹ gẹẹ, ki wọn le ma ri iṣẹ rere yin, ki wọn le maa yin baba yin ti n bẹ ni ọrun logo.” (Wo: Mátíù 5:16) Eyi tunmọ si pe Ọlọrun fẹ ki a gbe aye wa ni ọna ti yoo jẹ ki awọn eniyan ma jẹri wipe tirẹ ni a jẹ nitootọ, ki wọn si tun ma fi ogo fun orukọ rẹ. Eyi gan si ni lẹta Johanu kẹta da le lori. O da lori ki a ma rin irinajo Kirisitiẹni wa ni ọna ti yoo jẹ ki awọn eniyan jẹri wa si rere, ki wọn si ma tipasẹ wa fi ogo fun Ọlọrun.
KÍ NI Ẹ̀RÍ RẸ LÁÀRIN WỌN
Ta wa ni Johanu kọ lẹta yi si? Ki ni awọn nkan ti o sọ nipa ẹni naa ati fun ẹni naa? Ki si ni ẹkọ ti a ri kọ nipa nkan ti o sọ fun ẹni yi ati nipa rẹ? Ẹ ja ki a bẹrẹ si ni wo idahun si awọn ibere wọnyi ninu lẹta naa lati ẹsẹ ikinni, eyi ti o ka bayi:
“Alagba, Si Gayusi, olufẹ, ẹni ti mo fẹ ninu otitọ. Olufẹ, emi n gbadura pe ninu ohun gbogbo ki o le maa dara fun ọ, ki o si maa wa ni ilera, ani bi o ti dara fun ọkan rẹ. Nitori mo yọ gidigidi, nigba ti awọn arakunrin de ti wọn si jẹrii si iwa otitọ inu rẹ, ani bi iwọ ti n rin ninu otitọ. Emi ni ayọ ti o o tayọ, lati maa gbọ pe, awọn ọmọ mi n rin ninu otitọ. Olufẹ, iwọ n ṣe oloootọ ninu iṣẹ ti iwọ n ṣe fun awọn ti n ṣe ara, ati paapaa fun awọn ti n ṣe alejo. Ti wọn n jẹrii si ifẹ rẹ niwaju ijọ: bi iwọ ba n pese fun wọn ni ọna ajo wọn gẹgẹ bi o ti yẹ ninu Ọlọrun. Nitori pe nitori iṣẹ Kirisiti ni wọn ṣe jade lọ, laigba ohunkohun lọwọ awọn alaikọla. Nitori naa, o yẹ ki awa fi inu rere gba iru awọn wọnyi, ki awa le jẹ alabaṣiṣẹ pọ pẹlu otitọ.” (3Jòhánù 1-8)
Pẹlu akọle Johanu ninu lẹta yi, a ri wipe ọkunrin kan ti a n pe ni Gayusi ni o kọ lẹta yi si. Ta wa ni Gayusi yi? A ri wipe alagba ni ọkunrin yi jẹ ninu ijọ ti o wa nigba naa, bi ọrọ Johanu ti ṣe fi han. A si tun ri wipe bi ọmọ ninu Kirisiti ni Johanu ṣe mu.
Ki wa lo fa ti Johanu ṣe kọ lẹta si? Akọkọ, o kọ lẹta si nitori iroyin ti o gbọ nipa rẹ. Bi lẹta yi ti ṣe fi han, awọn ajiyinrere kan ti Gayusi fi igbakanri gba ni alejo ni o royin rẹ fun Johanu. Ki si ni wọn sọ nipa rẹ? Akọkọ, wọn jẹri pe o n rin ninu otitọ Kirisiti Jesu. Ekeji, wọn jẹrii si ifẹ rẹ ti o han si gbogbo ijọ Ọlọrun, eyi ti o si han si awọn naa pẹlu nipa itọju ati iranlọwọ ti o fun wọn ni akoko ti wọn de ba ni alejo. Awọn ẹri ti Johanu gbọ nipa Gayusi yi ni o jẹ ki inu rẹ dun debi wipe o mu awọn nkan ikọwe rẹ, o si kọ iwe si lati gbadura fun un. Adura rẹ si ni pe Ọlọrun jẹ ki o ma fi gbogbo igba dara fun, ni ọkan, ni ẹmi ati ni ara.
Njẹ awa ni awọn adari ijọ ati awọn ọmọ Ọlọrun ti o n fi igba gbogbo gbadura fun ilọsiwaju wa nitori awọn ẹri ti wọn n gbọ ati gba nipa wa? Iru ẹri wo ni awọn eniyan, paapaa julọ awọn ọmọ ijọ wa ati awọn ti o wa ni ayika wa, n jẹ nipa wa? Ṣe ẹri nipa iduro ṣinṣin wa ninu otitọ ati ifẹ Kirisiti ni abi ẹri nipa igbe aye agbere, ole, ọdaju tabi eke ṣiṣe ni? Lotitọ, awọn afọrọbatẹnija wa. Amọ, ti a ba n gbe igbe aye ti o wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun, ko si ki a ma ri ẹnikan tabi meji ti yoo gba ẹri wa jẹ, ti yoo si ma dupẹ lọwọ Ọlọrun nitori aye wa.
Idi keji ti Johanu fi kọ lẹta yi si Gayusi ni lati tun rọ ọ lati tẹsiwaju ninu iṣẹ rere ti o n ṣe, paapaa julọ si awọn ajiyinrere ati aṣoju awọn apọsiteli ti o n tọ ọ wa, eyi ti awọn eniyan n jẹrii rẹ. O si sọ idi ti o ṣe ṣe pataki fun lati ma tọju awọn iranṣẹ Ọlọrun wọnyi. Ki ni idi naa? Idi naa ni pe awọn iranṣẹ Ọlọrun yi ko gba iranlọwọ lati ọdọ awọn alaigbagbọ, bi o tilẹ jẹ wipe o ṣeeṣe ki a ri awọn alaigbagbọ ti o fẹ ran iṣẹ iranṣẹ wọn lọwọ. Awọn wọnyi ko dabi awọn ti o pe ara wọn ni ojiṣẹ Ọlọrun loni, ṣugbọn ti o jẹ pe gbogbo igba ni wọn n fi iwe fun iranlọwọ ranṣẹ si awọn alaigbagbọ, paapaa julọ awọn oloṣelu. Nitorina, nkan ti o tọ ni ki awọn ọmọ Ọlọrun ran wọn lọwọ ni ọna ti o tọ ati ti o yẹ.
Ẹkọ pataki ni awa naa si ri kọ lara eyi. O yẹ ki a ri daju pe a n tọju awọn iranṣẹ Ọlọrun ti o n lo fun wa ati awọn ti o n jade lati ọdọ wa lọ waasu iyinrere kaakiri agbaye. Eyi ko ni fi aye silẹ fun wọn lati ri awawi kankan fun gbigba ọna eru lati ma gba owo lọwọ awọn ọmọ Ọlọrun tabi lọwọ awọn ti ko mọ Ọlọrun rara. Bawo wa ni o ṣe mu eyi ni pataki to?
Johanu wa tẹsiwaju ninu lẹta yi lati pe akiyesi Gayusi si awọn meji kan ninu ijọ ti awọn naa jẹ alagba bi tirẹ ati iha ti o yẹ ki o kọ si wọn. Ẹni akọkọ laarin awọn meji yi ni o pe orukọ rẹ ni Diotirefe. Iwọ naa wo nkan ti o kọ nipa rẹ:
“Emi kọwe si ijọ: ṣugbọn Diotirefe, ẹni ti o fẹ lati jẹ ẹni pataki julọ, ko gba wa. Nitori naa bi mo ba de, emi yoo mu iṣẹ rẹ ti o ṣe wa si iranti rẹ, ti o n sọ ọrọ buburu ati isọkusọ si wa: eyi ko si tun tẹ ẹ lọrun, sibẹ oun funra rẹ kọ lati gba awọn ara, awọn ti o ṣi n fẹ gba wọn, o n da wọn lẹkun, o si n le wọn kuro ninu ijọ. Olufẹ, ma ṣe afarawe ohun ti i ṣe ibi bi ko ṣe ohun ti ṣe rere. Ẹni ti o ba n ṣe rere ti Ọlọrun ni, ẹni ti o ba n ṣe buburu ko ri Ọlọrun.” (3Johanu 9-11)
Ki ni a ri nipa Alagba Diotirefe? Akọkọ, a ri wipe adari ijọ Ọlọrun kan ni, ẹni ti Gayusi si mọ daradara. Nkan ekeji ti a ri nipa rẹ ni pe ko tẹriba fun aṣẹ awọn apọsiteli Kirisiti nitori pe o ka ara rẹ si ẹni pataki. Ẹkẹta, a ri wipe o n sọ isọkusọ nipa awọn apọsiteli Oluwa. Ẹkẹrin, ko tẹwọgba awọn ajinyinrere ati aṣoju awọn apọsiteli ti o wa sinu ijọ rẹ. Ẹkarun, o n ṣi aṣẹ rẹ gẹgẹ bi adari ijọ lo nipa lile awọn ọmọ ijọ rẹ ti o tẹwọgba awọn aṣoju awọn apọsiteli kuro ninu ijọ.
Bawo wa ni ti ọkunrin yi ṣe jẹ ti o fi kọ iru iha yi si awọn apọsiteli? Ki gan ni o fi ara rẹ pe? Ati wipe ọna wo lo gba di alagba ijọ gan? Pọọli apọsiteli ko kọ iru iha yi si awọn ti o jẹ apọsiteli ṣaaju rẹ. Dipo bẹẹ, nṣe ni o rẹ ara rẹ silẹ lati ba wọn lo pọ, ki wọn ba le tẹwọgba iṣẹ iranṣẹ rẹ. Wọn si tẹwọgba tọwọ-tẹṣẹ. Amọ Diotirefe jẹ onigberaga ọkan ati ẹnikan ti o fẹ lati jẹ gaba lori awọn ọmọ Ọlọrun. Nitorina ni ko ṣe ka awọn apọsiteli si nkan, ti o si n ṣe bi o ti ṣe wu. (Wo: Gàlátíà 2:1-10; 2Pétérù 3:15-16)
Nitorina, ko ki i ṣe tuntun ni lati ri awọn agberega alagba, alufa tabi wolii ninu ijọ, awọn ti ẹnu ko ni ka wọn mọ nigba ti wọn ba ti de ipo adari. Awọn ti wọn ba si wa ni ipo adari fun iru awọn wọnyi gbọdọ pe akiyesi awọn ọmọ Ọlọrun si nkan ti wọn n ṣe, ki wọn si tun ba wọn wi ni ọna ti o tọ, gẹgẹ bi Johanu ti ṣe ileri fun Gayusi pe oun yoo ṣe. Bi o si tilẹ wa jẹ wipe Gayusi ko si ni ipo lati ba Diotirefe wi, Johanu sọ fun pe ki o ma ṣe afarawe rẹ. Ti awa naa ba ri ẹnikẹni ninu ijọ ti ko rin ni ọna ti o tọ, a ko gbọdọ ṣe afarawe rẹ, bi a ko tilẹ si ni ipo lati ba a wi. Kiki ohun ti o ba jẹ rere ni ọmọ Ọlọrun gbọdọ ṣe afarawe rẹ.
Ẹnikeji ti Johanu pe akiyesi Gayusi si ni Demetirosi. Wo nkan ti o sọ nipa rẹ: “Demetirosi ni ẹri rere lọdọ gbogbo eniyan ati ni ti otitọ funra rẹ pẹlu; nitootọ, awa pẹlu si gba ẹri rẹ jẹ; ẹyin si mọ pe, otitọ ni ẹri wa.” (3Johanu 12) Ki ni idi ti o fi pe akiyesi Gayusi si ọkunrin yi? Idi naa ni ki o ba le ṣe afarawe rẹ. O ti kọkọ kilọ fun lati ma ṣe afarawe nkan ti ko dara, eyi ti o n jẹyọ ninu aye Diotirefe. O wa n gbe Demetirosi siwaju rẹ gẹgẹ bi ẹni ti o ni eri rere niwaju awọn ọmọ Ọlọrun gbogbo ati niwaju awọn apọsiteli rẹ. O ṣi n jẹ ki o ye e wipe otitọ ni ẹri awọn nipa ọkunrin yi, ko ki i ṣe ọrọ ori ahọn tabi ti oju aye. Nitorina, ẹni ti Gayusi le fi ṣe awọkọṣe ni.
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Njẹ awa naa jẹ ẹni ti awọn adari ijọ wa tabi awọn ọmọ Ọlọrun ti o wa ni ayika wa le tọka si gẹgẹ bi awọkọṣe rere bi? Ti awọn adari ijọ wa ba tilẹ nilo lati kọ lẹta nipa wa tabi sọrọ nipa wa fun awọn ẹlomiran, ki ni wọn yoo ri wi nipa wa? A sọrọ Gayusi ati Demetirosi daradara ninu lẹta yi. Njẹ a o le sọrọ awa na ni daradara ti a ba kọwe nipa wa? Ni ipari, Johanu sọ fun Gayusi wipe, “Emi ni ohun pupọ lati kọ sinu iwe si ọ, ṣugbọn emi ko fẹ kọ wọn sinu iwe. Mo ni ireti lati ri ọ laipẹ, ti awa yoo si sọrọ lojukoju. Alaafia fun ọ. Awọn ọrẹ wa to wa nibi ki ọ. Ki awọn ọrẹwa to wa nibẹ yẹn ni ọkọọkan.” (3Johanu 13-14)
ÌBÉÈRÈ
– Sọ nkan mẹta pataki ti o ri kọ ninu ẹkọ yi?
Lati ọwọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2023 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07025105978)
ÀKỌ́RÍ: ÌWÚLÒ ÒWE ÀLÌKÁMÀ ÀTI ÈPÒ FÚN ÌJỌ | ÀYỌKÀ: MATIU 13:24-30&36-43 | ỌJỌ́RÚ 15, ÈRÈLÉ 2023
ÀKỌ́SÓRÍ: “Emi ko sọ oore-ọfẹ Ọlọrun di asan: nitori pe, bi a ba ti ipasẹ ofin sọ eniyan di olododo, njẹ iku Kirisiti jẹ asan.” (Galatia 2:21)“Aye ni oko naa; irugbin rere ni awọn eniyan ti ijọba ọrun. Epo ni awọn eniyan ti wọn jẹ ti eṣu…” (Matiu 13:37)
Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ
Bi a ti ṣe sọ nigba ti a bẹrẹ ẹkọ ninu lẹta Pọọlu si awọn ara Galatia, apọsiteli yi kọ lẹta yi lati mu awọn ara Galatia pada sinu igbagbọ ninu Jesu Kirisiti gẹgẹ ọna kan ṣoṣo lati di ẹni igbala ati lati jẹ ẹni itẹwọgba niwaju Ọlọrun. O si ṣe eyi nitoripe awọn aṣinilọna kan ti wa si arin wọn, ti wọn si ti ṣi wọn lọna lati bẹrẹ si ni tẹle awọn abala ofin Mose kan gẹgẹ bi ọna lati di ẹni itẹwọgba niwaju Ọlọrun. Ki ero ati ifẹ awọn aṣinilọna yi ma ba wa ṣẹ lori awọn ara Galatia yi, o ni lati ṣalaye fun wọn lẹkunrẹrẹ iriri ti ara rẹ ki o to di Kirisitiẹni, iriri rẹ gẹgẹ bi Kirisitiẹni ni gbigbogun ti awọn ti o n fẹ lo ofin Mose lati fi idibajẹ sinu iyinrere Jesu, idi ti a ṣe fun awọn Juu ni ofin Mose, ibi ti ofin Mose pari iṣẹ rẹ si ati ewu ti o sọrọ mọ ki gbe Jesu ju si ẹgbẹ kan lati tẹle ofin Mose. Yoo wa ṣe wa ni anfaani pupọ lati mu awọn nkan ti o sọ lori awọn nkan wọnyi ni ọkunkundun ati lati ṣe amulo wọn ninu irinajo igbagbọ wa. Aijẹbẹ, o ṣeeṣe ki a bi wa wo lulẹ kuro ni ipo ominira ti a wa ninu Kirisiti.
ÌṢÒGO ARA
Wayi o, ninu abala lẹta yi ti a fẹ gbeyẹwo ninu ẹkọ yi, Pọọlu pari ọrọ rẹ nipa siso idi ti ọpọ awọn Kiritiẹni ti o jẹ Juu ṣe n ṣiṣẹ lati jẹ ki awọn Kirisitiẹni ti o jẹ Keferi le ma pa awọn abala ofin Mose kan mọn, paapaa julọ eyi ti o ni i ṣe pẹlu ikọla abẹ. Iwọ naa wo nkan ti o sọ:
“Ẹ wo o bi mo ti fi ọwọ ara mi kọwe gadagba-gadagba si yin. Iye awọn ti n fẹ ṣe aṣehan nipa ti ara, wọn n rọ yin lati kọla; kiki nitori pe ki a ma baa ṣe inunibini si wọn nitori agbelebuu Kirisiti. Nitori awọn ti a kọ nila paapaa ko pa ofin mọ, ṣugbọn wọn n fẹ mu yin kọla, ki wọn ki o le maa sogo ninu ara yin.” (Gálátíà 6:11-13)
Akọkọ naa, Pọọlu jẹ ki o ye awọn ara Galatia pe ohun funrara oun ni oun kọ lẹta yi si wọn, oun ko bẹ ẹnikẹni lati kọ. Idi si ni pe o fẹ ki wọn mọ pe ati ọdọ oun ni ohun gbogbo ti o mẹnuba ninu lẹta naa ti wa. Awọn kan ti wa titori eyi sọ wipe nitori oju ti o n dun apọsiteli yi ni o ṣe sọ eyi. Ko si ibi ti a ti fi ẹsẹ rẹ mulẹ ninu bibeli pe oju n dun Pọọlu. O ṣeeṣe ki oju ma a dun nitootọ. Amọ, niwọn igba ti a ko ti fi ẹsẹ rẹ mulẹ ninu bibeli pe oju n dun, a ko le sọ wipe nitori oju ti o n dun ni o ṣe kọwe gadagba-gadagba si wọn. Nitorina, oun ati awọn ara Galatia ni itumọ nkan ti o sọ yi ye. Eyi ti o kan awa n pe oun ni o kọ lẹta yi funrarẹ, ki o ba ma si ariyanjiyan kankan lori nkan ti o wa ninu rẹ.
O wa tẹsiwaju lati jẹ ki awọn ara Galatia mọ idi ti awọn ti wọn n rọ wọn lati kọ ila abẹ, ni ibamu pẹlu ofin Mose fun gbogbo awọn Ju ati awọn Keferi ti o ba fẹ darapọ mọ wọn lati jọsin Ọlọrun, ṣe n ṣe bẹ. Idi naa si ni pe wọn fẹ yẹra fun inunibini ti o sọrọ mọ iku, ajinde ati igbasoke Kirisiti. Iku Kirisiti ni ori-igi agbelebu ni o fi opin si ofin Mose ati egun ti o wa lori awọn ti o wa labẹ ofin yin. Nitorina, nitori iku Kirisiti lori igi agbelebu ni ko ṣe tọna fun ẹnikẹni lati tun ma pa ofin Mose mọ gẹgẹ bi ọna lati di ẹni igbala ati ẹni itẹwọgba niwaju Ọlọrun. Iku rẹ lori igi yi ati ajinde rẹ ti mojuto gbogbo nkan wọnyi.
Amọ awọn Juu ko ṣetan lati gba eyi rara. Nitorina, Juu yowu ti ko ba fẹ ṣẹ wọn ko gbọdọ sọ wipe bawo ni ti ofin Mose ti ṣe jẹ. Bẹẹ si ni Keferi yowu ti o ba fẹ ki awọn Juu tẹwọgba oun gẹgẹ bi ẹni ti o n sin Ọlọrun alaaye nitootọ ko gbọdọ sọ wipe bawo ni ti ila abẹ ṣe jẹ. Niwọn igba ti Keferi kan ba ti gba lati kọ ila abẹ, awọn Juu yoo yọnu si, wọn o si bẹrẹ si ni fi oju ẹni ti awọn le ba ṣe pọ wo o. Ṣugbọn ẹni ti ko ba tẹwọgba ofin Mose ni ọna yi ko le ni ajọsepọ ẹsin kankan pẹlu wọn. Ti ẹni naa ba wa lọ jẹ Juu, a jẹ wipe o gbọdọ mura fun oniruuru inunibini lati ọdọ wọn niyẹn, eyi ti o si le yọri si iku fun. Nitorina, Pọọlu fẹ ki o ye awọn ara Galatia pe nitori pe awọn Juu ti o n rọ wọn lati kọ ila abẹ n sa fun inunibini ni wọn ṣe n ṣe eyi.
Yatọ si iyẹn, Pọọlu tun jẹ ki o ye wọn pe awọn Juu yi n wa idi lati ma ṣogo le awọn Keferi lori ni wọn ṣe n sọ pe ki wọn kọ ila abẹ. Eyi tunmọ si pe wọn fẹ le ma yọ niwaju awọn Juu ti ko ki i ṣe Kirisitiẹni pe nipasẹ iwasu iyinrere Jesu ni awọn Keferi ti o gbagbọ ṣe n di ẹni ikọla. Wọn si tun fẹ ma lo eyi gẹgẹ bi awawi fun wọn lati ma ba awọn Keferi ni ajọṣepọ.
Amọ ṣe awọn gan funrawọn n pa awọn ofin Mose yoku mọ bi? Rara o. Ọpọ ninu wọn ni o ti mọ ni akoko yi pe ofin Mose ko le gba awọn la tabi sọ wọn di ẹni itẹwọgba niwaju Ọlọrun. Nitori eyi, wọn ko fi taratara mu ẹbọ lọ sinu Tẹmipili mọ. Ki lo wa fa ti wọn ṣe wa mura kankan pe ki awọn Keferi ma pa abala ofin yi ti o ni i ṣe pẹlu ikọla abẹ mọ, bi ko ṣe lati ma ṣogo asan le wọn lori? Ṣugbọn, ki ni ere ikọla abẹ fun awọn Keferi wọnyi ti o gbagbọ? Ṣe ila abẹ ti wọn kọ ni o ṣe pataki si Ọlọrun ni tabi atunbi ọkan wọn? Ṣe ikọla abẹ ni o ṣe pataki si Ọlọrun ni tabi igbe aye igbagbọ ti o n ṣiṣẹ pẹlu ifẹ?
Loni, awa Kirisitiẹni naa ni awọn nkankan ti a ma n fẹ lo lati ṣogo le awọn ti o ba ṣẹṣẹ n gbagbọ lori. Fun apẹrẹ, dipo ki fi ma yọ lori iṣẹ irapada ọkan wọn ati iyipada aye wọn ti Ọlọrun ṣe nipasẹ Jesu, a le ma yọ lori wipe wọn ko lo yẹtí etí tabi ẹ̀gbà ọrùn mọ. Tabi ki a ma yọ lori wipe wọn ti n wọ iru aṣọ ti a n wọ ninu ijọ wa tabi pe wọn n fi ede fọ, tabi pe wọn n wa si ipade awọn ọmọ Ọlọrun deede ati bẹẹbẹẹ lọ. Jesu funrarẹ si wa kilọ fun wa pe ki a ma ṣe yọ tabi ṣogo lori awọn nkan ti ko ni i ṣe pẹlu igbala ọkan awọn eniyan tabi iyipada aye wọn (Luuku 10:20). Idi si ni pe igbala ọkan awọn eniyan ni o jẹ Ọlọrun logun julọ. Eyi ni yo sọ irufẹ igbe aye ti wọn yoo ma gbe ati ibi ti wọn yoo pari ere ije wọn laye yi si.
Pọọlu wa sọ eyi fun wa nipa ara rẹ:
“Ṣugbọn ki a ma ṣe ri i, pe emi n ṣogo ninu ohun miiran, bi ko ṣe ninu agbelebuu Jesu Kirisiti Oluwa wa, nipasẹ ẹni ti a ti kan aye mọ agbelebu fun mi, ati emi fun aye. Nitori pe ninu Kirisiti Jesu ikọla tabi aikọla ko jẹ ohunkan, bi ko ṣe ẹda tuntun. Njẹ, ki alaafia Ọlọrun ati aanu wa pẹlu iye awọn ti n ṣe gẹgẹ bi ilana yii, ani Isiraẹli Ọlọrun.” (Gàlátíà 6:14-16)
Njẹ o ri bayi? Ko si idi fun isogo ara kankan lori ẹnikẹni ti o ba gba Jesu gbọ. Nkan ẹyọkan ṣoṣo ti a lẹtọ lati ṣogo le lori ni iṣẹ Jesu Kirisiti lori igi agbelebu fun gbogbo eniyan. Nipa iṣẹ rẹ ni a ṣe di oku si aye, ti aye si di oku si wa. Nitorina, niwọn igba ti eniyan ba si ti wa ninu Kirisiti, boya o kọ ila abẹ tabi ko kọ ọ, ko ja mọ nkankan niwaju Ọlọrun. Nkan ti o ṣe pataki julọ si Ọlọrun ni pe ẹna naa ti di ẹda tuntun. Bi Pọọlu ṣe wa tẹsiwaju lati sọ, awọn ti o ba n gbe aye wọn ni ibamu pẹlu ilana yi, awọn ti wọn mu didi ẹda tuntun ni pataki ni Isiraẹli Ọlọrun nitootọ. Awọn wọnyi naa si ni o tun sure fun pe ki alaafia ati aanu Ọlọrun ma wa pẹlu wọn titi lailai.
Ni akotan, Pọọlu wa sọ eyi:
“Lati isinsinyi lọ, ki ẹnikẹni ma ṣe yọ mi lẹnu mọ; nitori emi n ru apa Jesu Oluwa kiri ni ara mi. Ara, oore-ọfẹ, Jesu Kirisiti Oluwa wa, ki o wa pẹlu ẹmi yin. Amin.” (Gàlátíà 6:17-18)
Awọn wo ni Pọọlu n sọ pe ki wọn ma ṣe yọ oun lẹnu mọ? Awọn ti o n rọ awọn Keferi ti o gbagbọ ati awọn ti o n mu wọn ni tipatipa lati kọ ila abẹ tabi lati pa ofin yowu ti o le jẹ ninu ofin Mose mọ ni o n sọrọ nipa. Awọn ni o yọ iṣẹ iranṣẹ rẹ lẹnu. Awọn ni o kede iyinrere ajeji, ti ko si ki i ṣe iyinrere rara. O wa n jẹ ki o ye wọn wipe, bi oun tilẹ jẹ Juu, àpá tabi aami ila abẹ ko ja mọ nkankan loju oun nitori ko ja mọ nkankan loju Ọlọrun naa. Ti ẹnikẹni ba si fẹ ma tọka si apa ila abẹ ti o kọ, oun pẹlu le tọka si apa ila inunibini ti o wa lara rẹ nitori iyinrere Jesu. O wa ṣeni laanu pe ọpọ igba ni ailoye nkan ti Pọọlu n sọ nibi ma n jẹ ki awọn Kirisitiẹni miran na ma sọ wipe apa Kirisiti wa ni ara wọn. Ti ko ba ṣe wipe a ti jẹ ọ niya tabi ṣe o leṣe ri nitori Kirisiti, o ko lẹtọ lati sọ wipe apa Kirisiti wa lara rẹ. Irọ nla ni eyi yoo jẹ. Ṣe o si wa yẹ ki ọmọ Ọlọrun ma parọ? Ko yẹ rara.
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Ipo ti a wa laye yi tabi ẹya ti a ti wa ko ja mọ nkankan niwaju Ọlọrun. Nkan ẹyọkan ṣoṣo ti o ṣe pataki si ni ki a di ẹda tuntun. Ninu Kirisiti Jesu nikan si ni a ti le di ẹda tuntun. Nkan yowu ti a ba wa rọ awọn eniyan lati ma ṣe lati tẹ Ọlọrun lọrun tabi lati fun wa ni iwuri ati nkan lati ṣogo le lori ko ni itumọ niwaju Ọlọrun niwọn igba ti wọn ko ba i ti di ẹda tuntun ninu Kirisiti. Asan, omulẹmofo, lasan ni nkan naa yoo jasi niwaju Ọlọrun. Bẹẹ si ni pẹlu, iṣogo wa ati iwuri wa lori aye awọn eniyan bẹ ko ni ni itumọ tabi ere kankan lori.
IBEERE
– Kini idi ti didi ẹda tuntun ṣe ṣe pataki si Ọlọrun ju ohunkohun ti eniyan le ma ṣe fun un lọ?
– Ki ni o ṣe pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi?
Lati ọwọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2023 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of ÀKỌ́SÓRÍ: “Aye ni oko naa; irugbin rere ni awọn eniyan ti ijọba ọrun. Epo ni awọn eniyan ti wọn jẹ ti eṣu…” (Matiu 13:37)
Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ
O ṣeeṣe ki o ti ṣe alabapade fọọrọn kan ti o ṣe afihan adari ijọ kan ti o n fa irun abẹ awọn arabinrin ijọ rẹ melokan ni gbangba-gbangba ninu ipade ijọ rẹ kan. O si tun ṣeeṣe naa ki o ti ṣe alabapade fọọrọn miran ti o n ṣe afihan arabinrin kan ti o pe ara rẹ ni ojiṣẹ Ọlọrun, ti o si n fun awọn ọmọkunrin inu ijọ rẹ ni omi ọyan rẹ mu ni gbangba-gbangba ninu ipade wọn kan. Ti o ko ba tilẹ wa ti ṣe alabapade awọn fọọran yi, o ṣeeṣe ki o ti gbọ iroyin awọn alufa ijọ ti o n ba awọn ọmọ ijọ wọn sun tabi ti awọn adari ijọ ti o n lo àfọṣẹ tabi ti awọn ọmọ ijọ ti o n lu awọn ọmọ ijọ wọn miran ni jibiti tabi ti wọn n gbiyanju lati fi wọn ṣe oogun owo. Bawo ni irufẹ awọn wọnyi ati awọn miran ti wọn fi iwa ati iṣe jọ wọn ṣe de inu ijọ? Bawo ni awọn ole, awọn ajẹ, awọn alagbere, awọn apaniyan ati bẹẹbẹẹ lọ ṣe de inu ijọ, ti ko si si ẹni ti o fura si wọn ni igba ti wọn n wọle? Ki wa ni Ọlọrun n ṣe lori iru awọn wọnyi tabi ki ni o yẹ ki ijọ ṣe lori wọn? Ṣe a tilẹ le ṣe nkankan lati ya awọn ijọ wa ya irufẹ awọn eniyan yi tabi a ko le ṣe nkankan lati ya wa ya wọn?
ÌWÚLÒ ÒWE ÀLÌKÁMÀ ÀTI ÈPÒ FÚN ÌJỌ
Idahun si awọn ìbéèrè wọnyi ni a ri ninu owe kan ti Jesu Oluwa wa pa fun awọn ọmọ ẹyin rẹ nipa ijọba Ọlọrun. Owe naa lo lọ ba yi:
“Jesu tun pa owe miran fun wọn: “Ijọba ọrun dabi agbẹ kan ti o gbin irugbin rere si oko rẹ, ṣugbọn ni oru ọjọ kan, nigba ti o sun, ọta rẹ wa si oko naa o si gbin epo saarin alikama, o si ba tirẹ lọ. Nigba ti alikama naa bẹrẹ si dagba, ti o si so eso, nigba naa ni epo naa fi ara han. Awọn ọmọ ọdọ agbẹ naa wa, wọn sọ fun un pe, ‘Ọga, irugbin rere kọ ni iwọ ha gbin si oko rẹ ni? Bawo ni epo ṣe wa nibẹ nigba naa?’ “O sọ fun wọn pe, ‘Ọta ni o ṣe eyi.’ Awọn ọmọ ọdọ rẹ tun bi i pe, ‘Njẹ iwọ ha fẹ ki a fa epo naa tu kuro?’ O da wọn lohun pe, ‘Rara, nitori bi ẹyin ba n tu epo kuro, ẹ o tu alikama danu pẹlu rẹ. Ẹ jẹ ki awọn mejeeji maa dagba pọ, titi di asiko ikore. Emi yoo sọ fun awọn olukore naa lati kọkọ ṣa awọn epo kuro ki wọn si diwọn ni iti, ki a si sun wọn, ki wọn si ko alikama sinu aka mi.’” (Matiu 13:24-30)
Ki ni Jesu fi ijọba ọrun we ninu owe yi? O fi we agbẹ kan ti o gbin irugbin rere si oko rẹ, ṣugbọn ti ọta rẹ si tun wa gbin epo saarin irugbin rere ti o ti gbin, iyẹn nigba ti awọn eniyan ti sun lọ. Eyi n jẹ ki o ye wa wipe, ti a ba n sọrọ nipa ijọba Ọlọrun ninu aye yi, ko ki i ṣe ohun gbogbo ti o n lọ ninu rẹ naa ni o wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun. Ṣugbọn ni opin ohun gbogbo, ni opin aye yi, Ọlọrun yoo ri daju pe ohunkohun ti ko wa ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ ni a fa tu ti-gbongbo-ti-gbongbo kuro ninu ijọba rẹ.
Ni kukuru, lẹyin igba ti ọta ọkunrin agbẹ ti Jesu n sọrọ rẹ ninu owe yi ti gbin epo si arin alikama rẹ, awọn ọmọ iṣẹ rẹ pe akiyesi rẹ si nkan ti o ṣẹlẹ, wọn si tun bere lọwọ rẹ bo ya o fẹ ki a wọn la arin oko rẹ kọja lati fa gbogbo awọn epo ti o wa nibẹ tu. Ṣugbọn ko fi aye gba wọn. Ki si ni idi? Idi ti O fun wọn nipe o ṣeeṣe ki wọn fa awọn alikama tu nigba ti wọn n ba n fa awọn epo ti o wa ninu oko naa tu. Ṣe wọn ko wa ni ṣe nkankan si awọn epo yi rara ni? Wọn yoo ṣe nkan si wọn. Amọ eyi di igba ikore. Ni igba ikore, ko si ẹni ti yoo ṣi alikima mu si epo. Nitori naa, ni igba ikore gan an ni a o ya awọn epo kuro laarin alikama, ti a o si da ina sun wọn.
Bawo wa ni eyi ṣe ni nkankan ṣe pẹlu ijọba Ọlọrun? Tani epo? Tani alikama? Tani afurugbin rere? Ta si ni ọta rẹ? Tani awọn ọmọ ọdọ afurigbin rere? Ki ni oko? Ki ni asiko ikore? Awọn ibere ti o wa si ọkan awọn ọmọ ẹyin Jesu niyi nigba ti wọn gbọ owe naa. Wọn si mọ wipe ti ko ba ṣe pe O ba sọ itumọ rẹ fun wọn, ko si bi wọn ti ṣe le mọ ọn tabi mọ iwulo rẹ inu irinajo igbagbọ wọn. Nitori naa ni wọn ṣe pada tọ ọ lọ lati bere alaye lori owe naa. Iwọ naa wo nkan ti Matiu sọ nipa eyi:
“Lẹyin naa o si fi ọpọ eniyan silẹ lode, o wọ ile lọ. Awọn ọmọ-ẹyin rẹ tọ ọ wa, wọn wi pe, “Ṣalaye owe epo inu oko fun wa.” O si da wọn lohun pe, “Ọmọ Eniyan ni ẹni ti o n funrugbin rere. Aye ni oko naa; irugbin rere ni awọn eniyan ti ijọba ọrun. Epo ni awọn eniyan ti wọn jẹ ti eṣu, ọta ti o gbin awọn epo saarin alikama ni eṣu. Ikore ni opin aye, awọn olukore si ni awọn angẹli. Gẹgẹ bi a ti ko epo jọ, ti a si sun un ninu ina, bẹẹ gẹgẹ ni yoo ri ni igbẹyin aye. Ọmọ Eniyan yoo ran awọn angẹli rẹ, wọn yoo si ko gbogbo ohun to n mu ni dẹṣẹ kuro ni ijọba rẹ ati gbogbo eniyan buburu. Wọn yoo si sọ wọn si inu ina ileru, nibi ti ẹkun oun ipayinkeke yoo gbe wa. Nigba naa ni awọn olododo yoo maa ran bi oorun ni ijọba Baba wọn. Ẹni ti o ba leti, jẹ ki o gbọ.” (Matiu 13:36-43)
Ṣe o ri bayi pe Jesu ṣalaye itumọ owe yi lẹkunrẹrẹ. Nitori na, a ko nilo lati fun ni itumọ miran yatọ si eyi ti O ti fun. Ninu alaye rẹ si ni yi, a ri pe Oun funrarẹ ni afunrugbin rere. A si tun ri wipe aye yi ni oko naa ti O fun irugbin rere si. Ki si ni idi ti O ṣe funrugbin sinu aye yi? Idi ni wipe Oun ni O ni aye naa (Saamu 24:1). Awọn wo wa ni irugbin rere? Akojọpọ awọn ọmọ ijọba Ọlọrun ni irugbin rere ti O fun sinu aye. Awọn wo si ni irugbin buburu, iyẹn epo? Awọn ọmọ eṣu ni irugbin buburu. Eṣu si ni ọta ti o fun wọn sinu aye.
Nitorina, bi awọn ọmọ Ọlọrun ti ṣe wa ninu aye, ti wọn si n ṣe amulo ipese rẹ lati dagba soke lati so eso rere, naa ni awọn ọmọ eṣu wa ninu rẹ, ti awọn naa si n ṣe amulo ipese rẹ lati so eso buburu. Ki wa ni o de ti Ọlọrun ko wa jẹ ki awọn iranṣẹ rẹ, iyẹn awọn angẹli rẹ bi a ti fi han wa ninu owe yi, ma fa awọn irugbin buburu yi tu lẹṣẹkẹsẹ ti eṣu ba gbin wọn? A ṣa ri aridaju ninu itumọ owe yi ati awọn akọsilẹ inu bibeli miran pe ki a tilẹ to bi awọn eniyan ni Ọlọrun ti ma n mọ irufẹ irugbin ti wọn yoo jẹ, yala rere ni tabi buburu. Idi ti Ọlọrun ko ṣe ki i jẹ ki a fa awọn irugbin buburu tu lẹkẹsẹ ni pe a le pa awọn irugbin rere lara nigba ti a ba n fa wọn tu. Nitorina, yoo jẹ ki a fi wọn silẹ lati ma dagba pọ pẹlu awọn irugbin rere. Amọ nigba ti akoko ikore ba de, a o ya wọn sọtọ fun iparun.
Eyi wa n jẹ ki o ye wa ọkan pataki lara idi ti Ọlọrun ko ki i fi ṣe idajọ awọn ika eniyan ni kete ti a ba bi wọn tabi nigba ti wọn ba bẹrẹ si ni fi ara wọn han gẹgẹ bi ika eniyan. Ọlọrun ko ki i fẹ jẹ alaiṣẹ niya nibi ti O ba ti n jẹ ẹlẹṣẹ niya. Nitorina, niwọn igba ti ko ba ti le ṣe idajọ awọn ẹlẹṣẹ lalai jẹ wipe awọn olododo pin nibẹ, ko ni ṣe idajọ wọn. Yoo wulẹ duro de akoko ti o wọ tabi opin ohun gbogbo, iyẹn opin aye yi, ki O to ṣe.
Eyi ko wa tunmọ si pe ko ki i ṣe idajọ ẹlẹṣẹ rara ninu aye yi. Bi bibeli ti ṣe fi ye wa, ojoojumọ ni Ọlọrun n ṣe idajọ awọn ẹlẹṣẹ ninu aye yi (Sefanaya 3:5). O le ma kan awọn kan loni. Ṣugbọn yoo pada kan wọn naa ni. Ọna ti Ọlọrun wa n gba ṣe idajọ wọn ni ko ye ọpọlọpọ wa. A ma n ro wipe nipa pipa awọn eniyan tabi nipa kikọlu wọn pẹlu aisan tabi ajalu nikan ni Ọlọrun ma n gba ṣe idajọ wọn. Eyi ko si ri bẹ. Lotitọ, Ọlọrun le lo awọn nkan wọnyi lati ṣe idajọ awọn eniyan. Ṣugbọn ko ki i ṣe gbogbo igba ni O ma n lo wọn.
Ki a tilẹ sọ otitọ, ọpọ igba ni o jẹ wipe nipasẹ awọn alaṣẹ ni Ọlọrun ma n gba ṣe idajọ awọn eniyan (Roomu 13:1-6). Awọn igba miran si wa ti o jẹ wipe nipa fifi awọn eniyan silẹ lati ṣe ara wọn leṣe ni Ọlọrun ma n gba ṣe idajọ wọn (Roomu 1:18-32). Nitorina, idajọ awọn ọmọ eṣu n lọ lọwọlọwọ bayi ninu aye. Ṣugbọn o di opin aye yi ki idajọ wọn to waye lẹkunrẹrẹ.
Amọ ṣa o, owe ti Jesu sọ yi ko wa nipa ti aye yi nikan, iyẹn nipa ti awọn ọmọ Ọlọrun ti o wa ninu aye ati awọn ọmọ eṣu ti o wa pẹlu wọn. Owe yi tun wa nipa ijọ Jesu ti o wa ninu aye naa pẹlu. A ti mọ wipe eṣu ni o gbin gbogbo awọn eniyan buburu ti o wa ninu aye sinu rẹ. Bawo wa ni ti awọn eniyan buburu ti o wa ninu ijọ Ọlọrun ti ṣe jẹ? Ọna wo ni wọn gba de ibẹ? Eṣu naa ni o gbin awọn wọnyi sinu ijọ, bi o ti ṣe gbin awọn ti o wa ninu aye sinu aye.
Ki wa ni ifẹ Ọlọrun lori awọn wọnyi? Ṣe O fẹ ki awọn angẹli rẹ fi wọn silẹ ni, ki wọn ma fa wọn tu kuro ninu ijọ awọn eniyan rẹ? Bi Jesu ti ṣe fi ye wa, ko ki i ṣe ifẹ rẹ ni ki awọn eniyan rẹ jẹ iya pẹlu awọn ẹlẹṣẹ lọnakọna. Nitorina, niwọn igba ti ko ba i ti han gbangba pe irugbin eṣu ni awọn kan ninu ijọ rẹ, O le ma jẹ ki awọn angẹli rẹ fa wọn tu. Amọ ni kete ti o ba ti fi ara han pe irugbin esu ni wọn, bi ko tilẹ pasẹ fun awọn angẹli rẹ lati fa wọn tu, ireti rẹ ni pe ki awọn ọmọ rẹ ti oye ye ṣe idajọ awọn wọnyi ni ibamu pẹlu ọrọ rẹ. Idi si ni wipe ko fẹ ki abawọn kankan wa ninu ijọ rẹ. (Wo: Jòhánù 15:1-6; Éfésù 5:25-27; 1Pétérù 4:17)
Nkan ti a n sọ ni pe, bi otilẹ jẹ wipe Jesu ni ki awọn angẹli rẹ fi awọn ọmọ eṣu silẹ sinu aye lati ma dagba pọ pẹlu awọn ọmọ rẹ titi di akoko ikorẹ, ko tunmọ si pe ki a ma gbe igbesẹ lori wọn ti a ba ti ṣe idamọ wọn ninu ijọ. A nilo lati gbe igbesẹ lọri wọn bi Jesu funrarẹ ti ṣe fi ye wa ninu ọrọ rẹ ati nipasẹ awọn apọsiteli rẹ. Aijẹbẹ, idajọ rẹ le wa sori wa. (Wo: 1Kọrinti 5:2&11:17-32)
Irufẹ igbesẹ wo si ni o tọ fun wa lati gbe lori wọn? Akọkọ, a gbọdọ da wọn mọ. Ti a ko ba da wọn mọ, ko si bi a ṣe le gbe igbesẹ ti o tọ lori wọn. Bawo ni a wa ṣe le da wọn mọ? Jesu sọ eyi fun wọn nipa ọna ti a le gba da wọn mọ:
“Ẹ maa ṣọra fun awọn eke wolii ti wọn n tọ yin wa ni awọ aguntan, ṣugbọn ni inu wọn apanijẹ ikooko ni wọn. Nipa eso wọn ni ẹyin o fi mọ wọn. Njẹ eniyan ha le ka eso ajara lara igi ọgan tabi eso ọpọtọ lara ẹgun oṣuṣu? Bẹẹ ni gbogbo igi rere a maa so eso rere ṣugbọn igi buburu a maa so eso buburu. Igi rere ko le so eso buburu, bẹẹ ni igi buburu ko le so eso rere. Gbogbo igi ti ko ba so eso rere, a ge e lulẹ, a wọ ọ ju sinu ina. Nitori naa nipa eso wọn ni ẹyin yoo mọ wọn.” (Mátíù 7:15-20)
Ṣe o ri ọna miran ti Jesu gba ṣe apejuwe awọn epo ti o wa inu ijọ rẹ bayi? O pe wọn ni ikooko apanijẹ ti o gbe aṣọ aguntan wọ. Eyi tunmọ si pe awọn wọnyi ko darapọ mọ ijọ Ọlọrun ni ọna ti awọn eniyan yoo fi tete mọ pe eke ni wọn. Dipo eyi, wọn darapọ mọ ijọ gẹgẹ bi awọn ti o ti di atunbi ninu Jesu, ti ẹmi Ọlọrun si wa ninu wọn. Nitorina, wọn a ma fedefọ, sọtẹle, ṣe iṣẹ iwosan ati iṣẹ imularada, waasu, kọrin ati bẹẹbẹẹ lọ. Bawo ni a ṣe wa fẹ da wọn mọ? Nipa wiwo eso ti aye wọn n so ni. Awọn wọnyi ko ni amuyẹ lati so eso ẹmi. Wọn ko ni amuyẹ lati so eso ifẹ, irẹlẹ, igbagbọ, ododo, ifarajin, ikoraẹni-nijanu ati bẹẹbẹẹ lọ, bi o ti wu ki wọn tiraka to. Wọn ko tilẹ ni tiraka lati so eso ẹmi. Iṣẹ ẹran ara ni yoo ma jẹyọ ninu aye wọn. Ti a ba si wa ba wọn wi tabi kilọ fun wọn, nṣe ni wọn yoo da a si agidi tabi ija. Eleyi yoo si jẹ ki a ṣe idamọ wọn. (Wo: Mátíù 18:15-17; 1Kọ́ríntì 5; Títù 3:10-11)
Wayi o, Jesu nikan kọ ni o sọrọ nipa bi a ti ṣe le da awọn wọnyi mọ. Awọn apọsiteli rẹ naa ba wa sọrọ pupọ lori bi a ti ṣe le da wọn mọ. Ti a ba ti wa ṣe idamọ wọn tan, ki ni o ku? Gẹgẹ bi ọrọ Jesu, a gbọdọ kiyesara fun wọn. Kini eyi tumọ si? O tunmọ si pe a gbọdọ yẹra fun ibaṣepọ pẹlu wọn. O tun tunmọ si pe a gbọdọ pe akiyesi awọn ọmọ Ọlọrun yoku si irufẹ eniyan ti wọn jẹ, ki awọn naa ba le yẹra fun wọn. Eyi yoo si jaṣi idajọ lori wọn. (Wo: Róòmù 16:17-18; 1Kọ́ríntì 5; 2Pétérù 2; Júùdù).
Fun apẹrẹ, bi a ti ṣe ri ninu iwe Iṣe awọn apọsiteli, Simoni oṣo ko ri ibi farapamọ si ninu ijọ. Ni kiakia ni awọn apọsiteli tu aṣiri rẹ, ti wọn si fi han gẹgẹ bi eke Kirisitiẹni ti awọn ọmọ Ọlọrun gbọdọ yẹra fun. Ni afikun, ni kete ti Pọọlu ri mọ daju pe awọn ẹlẹkọ eke ati awọn ti iwa wọn lodi si ifẹ Ọlọrun ti wọ ijọ awọn ara Efesu ati ijọ awọn ara Kireti ni o ti sọ nkan ti Timoti ati Titu gbọdọ ṣe lati fi opin si iṣẹ wọn ninu ijọ. Nitorinaa, awa naa ko gbọdọ fi aye gba awọn eke onigbagbọ tabi wolii ni aarin wa ninu ijọ. Dipo eyi, a gbọdọ tan imọlẹ ṣi iṣẹ wọn, ki aṣiri wọn ba le tu. Aijẹbẹ, wọn yoo fi idibijẹ si aarin wa. Eyi si le jẹ ki idajọ Ọlọrun wa si wa lori. (Wo: Ìṣe Àpọ́sítélì 8:9-24; 1Tímótì 1&4; Títù 1; Ìfihàn 2:18-29)
Ọ̀RỌ ÌPARÍ
Bi o tilẹ jẹ wipe ko ki i ṣe awọn ọmọ ijọba Ọlọrun nikan ni o wa ninu aye yi, Ọlọrun ko ni fa gbogbo awọn ọmọ eṣu ati iṣẹ ọwọ wọn ti o n lọ nibẹ tu ni kiakia ti opin aye ko ba i ti de. Idi niyi ti o fi jẹ wipe ko si bi ijọba wa ṣe le dara ati ni ifẹ ododo to, ti yoo le fa gbogbo awọn ọmọ eṣu tu kuro laye. Amọ ninu ijọ Ọlọrun, a ko gbọdọ fi aye gba awọn ọmọ eṣu lati gberu ni aarin wa. Aijẹbẹ, wọn yoo pa igbagbọ ati aye wa lara ni ọna ti ko ṣe fẹnu sọ. Nitorinaa, a gbọdọ kiyesara lati da wọn mọ ati lati ma ṣe idajọ wọn ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun.
IBEERE
– Ki ni anfaani owe ti a gbeyẹwo ninu ẹkọ yi fun awọn ọmọ Ọlọrun?
– Ki ni o ṣe pataki julọ si ọ ninu ẹkọ naa.
Lati ọwọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2023 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07025105978)
ÀKỌ́RÍ: Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ GÀLÁTÍÀ | ÀYỌKÀ: GÀLÁTÍÀ 6:11-18 | ỌJỌ́RÚ 08, ÈRÈLÉ 202
ÀKỌ́SÓRÍ: “Emi ko sọ oore-ọfẹ Ọlọrun di asan: nitori pe, bi a ba ti ipasẹ ofin sọ eniyan di olododo, njẹ iku Kirisiti jẹ asan.” (Galatia 2:21)
Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ
Bi a ti ṣe sọ nigba ti a bẹrẹ ẹkọ ninu lẹta Pọọlu si awọn ara Galatia, apọsiteli yi kọ lẹta yi lati mu awọn ara Galatia pada sinu igbagbọ ninu Jesu Kirisiti gẹgẹ ọna kan ṣoṣo lati di ẹni igbala ati lati jẹ ẹni itẹwọgba niwaju Ọlọrun. O si ṣe eyi nitoripe awọn aṣinilọna kan ti wa si arin wọn, ti wọn si ti ṣi wọn lọna lati bẹrẹ si ni tẹle awọn abala ofin Mose kan gẹgẹ bi ọna lati di ẹni itẹwọgba niwaju Ọlọrun. Ki ero ati ifẹ awọn aṣinilọna yi ma ba wa ṣẹ lori awọn ara Galatia yi, o ni lati ṣalaye fun wọn lẹkunrẹrẹ iriri ti ara rẹ ki o to di Kirisitiẹni, iriri rẹ gẹgẹ bi Kirisitiẹni ni gbigbogun ti awọn ti o n fẹ lo ofin Mose lati fi idibajẹ sinu iyinrere Jesu, idi ti a ṣe fun awọn Juu ni ofin Mose, ibi ti ofin Mose pari iṣẹ rẹ si ati ewu ti o sọrọ mọ ki gbe Jesu ju si ẹgbẹ kan lati tẹle ofin Mose. Yoo wa ṣe wa ni anfaani pupọ lati mu awọn nkan ti o sọ lori awọn nkan wọnyi ni ọkunkundun ati lati ṣe amulo wọn ninu irinajo igbagbọ wa. Aijẹbẹ, o ṣeeṣe ki a bi wa wo lulẹ kuro ni ipo ominira ti a wa ninu Kirisiti.
ÌṢÒGO ARA
Wayi o, ninu abala lẹta yi ti a fẹ gbeyẹwo ninu ẹkọ yi, Pọọlu pari ọrọ rẹ nipa siso idi ti ọpọ awọn Kiritiẹni ti o jẹ Juu ṣe n ṣiṣẹ lati jẹ ki awọn Kirisitiẹni ti o jẹ Keferi le ma pa awọn abala ofin Mose kan mọn, paapaa julọ eyi ti o ni i ṣe pẹlu ikọla abẹ. Iwọ naa wo nkan ti o sọ:
“Ẹ wo o bi mo ti fi ọwọ ara mi kọwe gadagba-gadagba si yin. Iye awọn ti n fẹ ṣe aṣehan nipa ti ara, wọn n rọ yin lati kọla; kiki nitori pe ki a ma baa ṣe inunibini si wọn nitori agbelebuu Kirisiti. Nitori awọn ti a kọ nila paapaa ko pa ofin mọ, ṣugbọn wọn n fẹ mu yin kọla, ki wọn ki o le maa sogo ninu ara yin.” (Gálátíà 6:11-13)
Akọkọ naa, Pọọlu jẹ ki o ye awọn ara Galatia pe ohun funrara oun ni oun kọ lẹta yi si wọn, oun ko bẹ ẹnikẹni lati kọ. Idi si ni pe o fẹ ki wọn mọ pe ati ọdọ oun ni ohun gbogbo ti o mẹnuba ninu lẹta naa ti wa. Awọn kan ti wa titori eyi sọ wipe nitori oju ti o n dun apọsiteli yi ni o ṣe sọ eyi. Ko si ibi ti a ti fi ẹsẹ rẹ mulẹ ninu bibeli pe oju n dun Pọọlu. O ṣeeṣe ki oju ma a dun nitootọ. Amọ, niwọn igba ti a ko ti fi ẹsẹ rẹ mulẹ ninu bibeli pe oju n dun, a ko le sọ wipe nitori oju ti o n dun ni o ṣe kọwe gadagba-gadagba si wọn. Nitorina, oun ati awọn ara Galatia ni itumọ nkan ti o sọ yi ye. Eyi ti o kan awa n pe oun ni o kọ lẹta yi funrarẹ, ki o ba ma si ariyanjiyan kankan lori nkan ti o wa ninu rẹ.
O wa tẹsiwaju lati jẹ ki awọn ara Galatia mọ idi ti awọn ti wọn n rọ wọn lati kọ ila abẹ, ni ibamu pẹlu ofin Mose fun gbogbo awọn Ju ati awọn Keferi ti o ba fẹ darapọ mọ wọn lati jọsin Ọlọrun, ṣe n ṣe bẹ. Idi naa si ni pe wọn fẹ yẹra fun inunibini ti o sọrọ mọ iku, ajinde ati igbasoke Kirisiti. Iku Kirisiti ni ori-igi agbelebu ni o fi opin si ofin Mose ati egun ti o wa lori awọn ti o wa labẹ ofin yin. Nitorina, nitori iku Kirisiti lori igi agbelebu ni ko ṣe tọna fun ẹnikẹni lati tun ma pa ofin Mose mọ gẹgẹ bi ọna lati di ẹni igbala ati ẹni itẹwọgba niwaju Ọlọrun. Iku rẹ lori igi yi ati ajinde rẹ ti mojuto gbogbo nkan wọnyi.
Amọ awọn Juu ko ṣetan lati gba eyi rara. Nitorina, Juu yowu ti ko ba fẹ ṣẹ wọn ko gbọdọ sọ wipe bawo ni ti ofin Mose ti ṣe jẹ. Bẹẹ si ni Keferi yowu ti o ba fẹ ki awọn Juu tẹwọgba oun gẹgẹ bi ẹni ti o n sin Ọlọrun alaaye nitootọ ko gbọdọ sọ wipe bawo ni ti ila abẹ ṣe jẹ. Niwọn igba ti Keferi kan ba ti gba lati kọ ila abẹ, awọn Juu yoo yọnu si, wọn o si bẹrẹ si ni fi oju ẹni ti awọn le ba ṣe pọ wo o. Ṣugbọn ẹni ti ko ba tẹwọgba ofin Mose ni ọna yi ko le ni ajọsepọ ẹsin kankan pẹlu wọn. Ti ẹni naa ba wa lọ jẹ Juu, a jẹ wipe o gbọdọ mura fun oniruuru inunibini lati ọdọ wọn niyẹn, eyi ti o si le yọri si iku fun. Nitorina, Pọọlu fẹ ki o ye awọn ara Galatia pe nitori pe awọn Juu ti o n rọ wọn lati kọ ila abẹ n sa fun inunibini ni wọn ṣe n ṣe eyi.
Yatọ si iyẹn, Pọọlu tun jẹ ki o ye wọn pe awọn Juu yi n wa idi lati ma ṣogo le awọn Keferi lori ni wọn ṣe n sọ pe ki wọn kọ ila abẹ. Eyi tunmọ si pe wọn fẹ le ma yọ niwaju awọn Juu ti ko ki i ṣe Kirisitiẹni pe nipasẹ iwasu iyinrere Jesu ni awọn Keferi ti o gbagbọ ṣe n di ẹni ikọla. Wọn si tun fẹ ma lo eyi gẹgẹ bi awawi fun wọn lati ma ba awọn Keferi ni ajọṣepọ.
Amọ ṣe awọn gan funrawọn n pa awọn ofin Mose yoku mọ bi? Rara o. Ọpọ ninu wọn ni o ti mọ ni akoko yi pe ofin Mose ko le gba awọn la tabi sọ wọn di ẹni itẹwọgba niwaju Ọlọrun. Nitori eyi, wọn ko fi taratara mu ẹbọ lọ sinu Tẹmipili mọ. Ki lo wa fa ti wọn ṣe wa mura kankan pe ki awọn Keferi ma pa abala ofin yi ti o ni i ṣe pẹlu ikọla abẹ mọ, bi ko ṣe lati ma ṣogo asan le wọn lori? Ṣugbọn, ki ni ere ikọla abẹ fun awọn Keferi wọnyi ti o gbagbọ? Ṣe ila abẹ ti wọn kọ ni o ṣe pataki si Ọlọrun ni tabi atunbi ọkan wọn? Ṣe ikọla abẹ ni o ṣe pataki si Ọlọrun ni tabi igbe aye igbagbọ ti o n ṣiṣẹ pẹlu ifẹ?
Loni, awa Kirisitiẹni naa ni awọn nkankan ti a ma n fẹ lo lati ṣogo le awọn ti o ba ṣẹṣẹ n gbagbọ lori. Fun apẹrẹ, dipo ki fi ma yọ lori iṣẹ irapada ọkan wọn ati iyipada aye wọn ti Ọlọrun ṣe nipasẹ Jesu, a le ma yọ lori wipe wọn ko lo yẹtí etí tabi ẹ̀gbà ọrùn mọ. Tabi ki a ma yọ lori wipe wọn ti n wọ iru aṣọ ti a n wọ ninu ijọ wa tabi pe wọn n fi ede fọ, tabi pe wọn n wa si ipade awọn ọmọ Ọlọrun deede ati bẹẹbẹẹ lọ. Jesu funrarẹ si wa kilọ fun wa pe ki a ma ṣe yọ tabi ṣogo lori awọn nkan ti ko ni i ṣe pẹlu igbala ọkan awọn eniyan tabi iyipada aye wọn (Luuku 10:20). Idi si ni pe igbala ọkan awọn eniyan ni o jẹ Ọlọrun logun julọ. Eyi ni yo sọ irufẹ igbe aye ti wọn yoo ma gbe ati ibi ti wọn yoo pari ere ije wọn laye yi si.
Pọọlu wa sọ eyi fun wa nipa ara rẹ:
“Ṣugbọn ki a ma ṣe ri i, pe emi n ṣogo ninu ohun miiran, bi ko ṣe ninu agbelebuu Jesu Kirisiti Oluwa wa, nipasẹ ẹni ti a ti kan aye mọ agbelebu fun mi, ati emi fun aye. Nitori pe ninu Kirisiti Jesu ikọla tabi aikọla ko jẹ ohunkan, bi ko ṣe ẹda tuntun. Njẹ, ki alaafia Ọlọrun ati aanu wa pẹlu iye awọn ti n ṣe gẹgẹ bi ilana yii, ani Isiraẹli Ọlọrun.” (Gàlátíà 6:14-16)
Njẹ o ri bayi? Ko si idi fun isogo ara kankan lori ẹnikẹni ti o ba gba Jesu gbọ. Nkan ẹyọkan ṣoṣo ti a lẹtọ lati ṣogo le lori ni iṣẹ Jesu Kirisiti lori igi agbelebu fun gbogbo eniyan. Nipa iṣẹ rẹ ni a ṣe di oku si aye, ti aye si di oku si wa. Nitorina, niwọn igba ti eniyan ba si ti wa ninu Kirisiti, boya o kọ ila abẹ tabi ko kọ ọ, ko ja mọ nkankan niwaju Ọlọrun. Nkan ti o ṣe pataki julọ si Ọlọrun ni pe ẹna naa ti di ẹda tuntun. Bi Pọọlu ṣe wa tẹsiwaju lati sọ, awọn ti o ba n gbe aye wọn ni ibamu pẹlu ilana yi, awọn ti wọn mu didi ẹda tuntun ni pataki ni Isiraẹli Ọlọrun nitootọ. Awọn wọnyi naa si ni o tun sure fun pe ki alaafia ati aanu Ọlọrun ma wa pẹlu wọn titi lailai.
Ni akotan, Pọọlu wa sọ eyi:
“Lati isinsinyi lọ, ki ẹnikẹni ma ṣe yọ mi lẹnu mọ; nitori emi n ru apa Jesu Oluwa kiri ni ara mi. Ara, oore-ọfẹ, Jesu Kirisiti Oluwa wa, ki o wa pẹlu ẹmi yin. Amin.” (Gàlátíà 6:17-18)
Awọn wo ni Pọọlu n sọ pe ki wọn ma ṣe yọ oun lẹnu mọ? Awọn ti o n rọ awọn Keferi ti o gbagbọ ati awọn ti o n mu wọn ni tipatipa lati kọ ila abẹ tabi lati pa ofin yowu ti o le jẹ ninu ofin Mose mọ ni o n sọrọ nipa. Awọn ni o yọ iṣẹ iranṣẹ rẹ lẹnu. Awọn ni o kede iyinrere ajeji, ti ko si ki i ṣe iyinrere rara. O wa n jẹ ki o ye wọn wipe, bi oun tilẹ jẹ Juu, àpá tabi aami ila abẹ ko ja mọ nkankan loju oun nitori ko ja mọ nkankan loju Ọlọrun naa. Ti ẹnikẹni ba si fẹ ma tọka si apa ila abẹ ti o kọ, oun pẹlu le tọka si apa ila inunibini ti o wa lara rẹ nitori iyinrere Jesu. O wa ṣeni laanu pe ọpọ igba ni ailoye nkan ti Pọọlu n sọ nibi ma n jẹ ki awọn Kirisitiẹni miran na ma sọ wipe apa Kirisiti wa ni ara wọn. Ti ko ba ṣe wipe a ti jẹ ọ niya tabi ṣe o leṣe ri nitori Kirisiti, o ko lẹtọ lati sọ wipe apa Kirisiti wa lara rẹ. Irọ nla ni eyi yoo jẹ. Ṣe o si wa yẹ ki ọmọ Ọlọrun ma parọ? Ko yẹ rara.
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Ipo ti a wa laye yi tabi ẹya ti a ti wa ko ja mọ nkankan niwaju Ọlọrun. Nkan ẹyọkan ṣoṣo ti o ṣe pataki si ni ki a di ẹda tuntun. Ninu Kirisiti Jesu nikan si ni a ti le di ẹda tuntun. Nkan yowu ti a ba wa rọ awọn eniyan lati ma ṣe lati tẹ Ọlọrun lọrun tabi lati fun wa ni iwuri ati nkan lati ṣogo le lori ko ni itumọ niwaju Ọlọrun niwọn igba ti wọn ko ba i ti di ẹda tuntun ninu Kirisiti. Asan, omulẹmofo, lasan ni nkan naa yoo jasi niwaju Ọlọrun. Bẹẹ si ni pẹlu, iṣogo wa ati iwuri wa lori aye awọn eniyan bẹ ko ni ni itumọ tabi ere kankan lori.
IBEERE
– Kini idi ti didi ẹda tuntun ṣe ṣe pataki si Ọlọrun ju ohunkohun ti eniyan le ma ṣe fun un lọ?
– Ki ni o ṣe pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi?
Lati ọwọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2023 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07025105978)
ÀKỌ́SÓRÍ: “Emi ko sọ oore-ọfẹ Ọlọrun di asan: nitori pe, bi a ba ti ipasẹ ofin sọ eniyan di olododo, njẹ iku Kirisiti jẹ asan.” (Galatia 2:21)
(Galatia 2:21)
Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ
Ninu ẹkọ ti a kọ kẹyin ninu lẹta Pọọlu si awọn ara Galatia, a ri iha ti o yẹ ki a kọ si awọn ara wa ninu Kirisiti ti o ba ṣubu sinu ẹṣẹ. Iha wo si ni o yẹ ki a kọ si wọn? Iha imupadabọsipo ni o yẹ ki a kọ si wọn. Eyi tunmọ si pe ojuṣe wa ni lati ri daju pe iru awọn Kirisitiẹni bẹ ko ku tabi sọnu patapata sinu ẹṣẹ. Ki eleyi wa to o ṣeeṣe, awa ti a fẹ mu wọn padabọsipo gbọdọ jẹ ẹni ti o n tẹle itọni Ẹmi Ọlọrun, onisuuru ati onirẹlẹ. Aijẹbẹ, o ṣeeṣe ki a ba nkan jẹ ju bi o ti ṣe wa lọ. Amọ bi a tun ti ṣe kọ ninu ẹkọ yi, ko pọn dandan ki ẹnikẹni ninu wa ṣubu sinu ẹṣẹ. Ti gbogbo wa ba tilẹ mura gidigidi lati jẹ alabaapin ninu aye awọn ọmọ ijọ wa, ọpọ igba ni Ọlọrun yoo ri wa lo lati dena ki wọn ko sinu pakute ẹṣẹ. Ṣugbọn ti a ba gbe igberaga wọ bi ẹwu, ti a ko si ṣetan lati ba awọn ọmọ Ọlọrun ti o wa ninu aye wa ṣe pọ tabi lati fi aye gba wọn lati mọ bi nkan ti ṣe n lọ ninu aye wa, ko si ni ki Satani ma ri wa ya sọtọ ni awọn abala aye wa kan lati fi iya jẹ wa tabi lati sọ igbagbọ wa di igbagbe.
ÌGBÉRAẸNI-NÍGBỌ̀NWỌ́
Ori ọrọ yi si tun ni Pọọlu wa ninu abala lẹta rẹ si awọn ara Galatia ti a fẹ gbe yẹwo ninu ẹkọ yi. Nkan ti o si fẹ ki o ye awọn ọmọ Ọlọrun yi naa ni pataki ki wọn ma gbe ara wọn ni igbọnwọ ninu irinajo wọn. Lotitọ, olukuluku ọmọ Ọlọrun ni yoo dahun funrarẹ nigba ti Ọlọrun ba n ṣe idajọ. Ko si si ẹnikankan ninu wa ti yoo ni awijare tabi ti yoo le sọ wipe oun kuna nitori aṣiṣe awọn kan tabi nitoripe oun ko ni onigbọnwọ. Nitorina, ẹnikọọkan wa gbọdọ mura lati mojuto ohun gbogbo ti o ba jẹ ojuṣe rẹ lati tẹ Ọlọrun lọrun ninu gbogbo ibaṣepọ rẹ, yala o ri ẹni ti yoo ran an lọwọ tabi ko ri.
Sibẹsibẹ, ifẹ Ọlọrun ni ki ẹnikọọkan wa ma fi gbogbo igba duro bi oluranlọwọ fun awọn ara wa. Aijẹbẹ, a ko ni mu ofin Kirisiti ṣẹ. Eyi si le jẹ ki a jẹbi iṣubu tabi ikuna awọn ara wa kan tabi omiran. Idi niyi ti Pọọlu ṣe sọ wipe ki ẹnikọọkan wa gbe igberaga ju sigbo, ki a si dẹkun lati ma ri ara wa ni bàbàrà, ki Ọlọrun ba le ri wa lo lati ma gbe awọn ara wa ninu Kirisiti nigbọnwọ. Iwọ naa wo nkan ti o sọ:
“Nitori bi eniyan kan ba n ro ara rẹ si ẹni pataki kan, nigba ti ko jẹ nnkan, o n tan ara rẹ jẹ. Ṣugbọn ki olukuluku ki o yẹ iṣẹ ara rẹ wo, nigba naa ni yoo si ni ohun isogo nipa ti ara rẹ nikan, ki yoo si ṣe nipa ti ọmọnikeji rẹ. Nitori olukuluku ni yoo ru ẹru ara rẹ. Ṣugbọn ki ẹni ti a n kọ ninu ọrọ naa maa ṣe alabaapin ohun rere gbogbo ti o ni fun ẹni ti o n kọ ọ.” (Gàlátíà 6:3-6)
Njẹ o ri bayi? Igberaga ni o ma n fa ti awọn ọmọ Ọlọrun ko ki i fi ba ara wọn ṣepọ lọna ti o tọ ati ti o yẹ. Niwọn igba ti wọn ko ba si ni ibaṣepọ ti o munadoko laarin ara wọn, ko si bi wọn ṣe le ran ara wọn lọwọ lọna ti o peye. Ki wa lo n fa irufẹ igberaga yi? Nkan kan gbogi ti o ma n fa naa ni ki a ma fi iṣẹ́ igbagbọ wa we ti awọn ọmọ Ọlọrun miran. Eyi ni o le jẹ ki a ka ara wa si ẹni pataki niwaju ara wa, nigba ti a ko si ja mọ nkankan laisi Ọlọrun.
Ko si idi kankan lati fi iṣẹ igbagbọ wa we ti ẹnikẹni. Ti a ba n ṣe agbeyẹwo iṣẹ wa, nṣe ni o yẹ ki a ma ṣe ni ibamu pẹlu ireti Ọlọrun lori rẹ. Ti a ba si n ṣe agbeyẹwo irinajo igbagbọ wa bakanna, nṣe ni o yẹ ki a ma ṣe ni ibamu pẹlu nkan ti Ọlọrun n reti lati ọdọ wa. Eyi jasi pe a ko gbọdọ ma wo aago-alaago sare tabi wo iṣẹ oniṣẹ ṣiṣẹ. Eyi ni ko ni jẹ ki a ba ẹnikẹni ninu ijọ wa lo pẹlu ọkan igberaga tabi pẹlu ọkan ẹni ti ko ja mọ nkankan niwaju Ọlọrun.
Gbogbo wa ni a ṣe pataki si Ọlọrun ati si ijọba rẹ. Idi si niyi ti o ṣe jẹ wipe gbogbo wa ni o ran ọmọ rẹ Jesu Kirisiti lati rapada. O ṣeeṣe, lotitọ, ki oye bi a ti ṣe n gbe aye tẹ ẹ lọrun tete ye awa kan ju awọn kan lọ, eyi ko tunmọ si pe a ṣe pataki ju awọn wọnyi lọ niwaju rẹ. Nitori eyi, ọna ti a o gba ma ran igbagbọ ati aye wọn lọwọ ni a gbọdọ ma fi gbogbo igba san, ko ki i ṣe bi a o ti ṣe fi ẹnu tẹnbẹlu wọn tabi ja wọn kulẹ.
Bi mo ti ṣe wa sọ siwaju, wipe a gbọdọ ma ran ara wa lọwọ ninu ijọ ko tunmọ si pe ki a wa sọ ara wa di bukata fun awọn ọmọ Ọlọrun miran. Ko tunmọ si pe ki a fi ojuṣe adura gbigba wa, ojuṣe mimọ ifẹ Ọlọrun wa tabi awọn ojuṣe itọju ile wa kọ awọn ọmọ Ọlọrun miran lọrun. Eyi ko bojumu rara, ko si wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun fun wa. Ki a tilẹ sọ otitọ, imọtaraẹninikan ni yoo jẹ ki a ṣe eleyi. O si lewu fun igbagbọ wa. Nitorina, gẹgẹ bi Pọọlu ṣe wi, ẹnikọọkan gbọdọ mura lati gbe bukata rẹ, lalai duro de ẹnikẹni fun iranwọ.
Amọ ṣa o, Pọọlu tun wa la ọrọ rẹ, ki a ma ba ṣi i tunmọ. Lọna wo? O jẹ ki o ye wa pe bi o tilẹ jẹ wipe ẹnikọọkan ninu ijọ Ọlọrun gbọdọ mura lati gbe ẹru aye rẹ, eyi ko jasi pe ki a pa awọn ti o n fi ọrọ Ọlọrun bọ wa ti ṣẹgbẹ kan, ki a si ọ pe ki awọn naa lọ ma mojuto bukata wọn funra wọn. Dipo eyi, a gbọdọ mọ pe ara ojuṣe wa ni lati ma a pin awọn ti o n fi ọrọ Ọlọrun bọ wa ninu ohun rere gbogbo ti a ba n rigba lọwọ rẹ. Ko yẹ ki a gbagbe pe awọn wọnyi ni o n kọ wa ni ọrọ Ọlọrun ti a n mulo ti aye wa fi n lọ deede. Nitorinaa, aṣẹ Ọlọrun ni pe bi aye wa ti n tipasẹ wọn lọ deede naa ni o yẹ ki a ma tọju wọn pẹlu awọn nkan ini wa. (Wo:1Kọrinnti 9:14)
Yatọ si eyi, ti enikan ba tọ wa sọna nipa ti ara, ti itọsọna rẹ si ja si igbega tabi ọrọ fun wa, ṣe ko yẹ ki a fi ẹmi imoore han siru ẹni bẹ ẹ? O yẹ! Nitorinaa, ma ṣe jẹ ki o ni ọ lara rara lati ma fifun awọn ti o n bọ ọ pẹlu ọrọ Ọlọrun, ti o si n ṣọna ninu adura lori aye rẹ, ni ibamu pẹlu bi a ti ṣe bukun fun ọ. O lere lori pupọ. (Wo: Numeri 10:29-3)
Eyi lo si fa ti Pọọlu fi tẹsiwaju lati sọ awọn ọrọ pataki yi fun wa lori fififunni:
“Ki a ma ṣe tan yin jẹ; a ko le gan Ọlọrun: nitori ohunkohun ti eniyan ba funrugbin, oun ni yoo ka. Nitori ẹni ti o ba n funrugbin sipa ti ara rẹ, nipa ti ara ni yoo ka idibajẹ; ṣugbọn ẹni ti o ba n funrugbin sipa ti Ẹmi, nipa ti Ẹmi ni yoo ka iye ainipẹkun. Ẹ ma si jẹ ki agara da wa ni rere e ṣe: nitori a yoo kaa nigba ti akoko ba de, bi a ko ba rẹwẹsi. Njẹ bi a ti n ri akoko, ẹ jẹ ki a maa ṣoore fun gbogbo eniyan, ati paapaa fun awọn ti i ṣe ara wa ninu igbagbọ.” (Gàlátíà 6:7-10)
Njẹ o ri bayi? Wipe Ọlọrun fẹ ki a ma fifun awọn ti o n bọ wa pẹlu ọrọ rẹ, ti o si n ṣọna lori aye wa, ati awọn miran ti O pa wa lasẹ lati ma fifun ko tunmọ si pe ki a kan ṣe bi a ba ti ṣe fẹ. Alakalẹ fififunni wa ninu iwe mimọ ti a gbọdọ tẹle. Aijẹbẹ, a kan tan ara wa jẹ ni – ififunni wa ko ni ni ere kankan lori. Bi Pọọlu ti ṣe fi ye wa ninu awọn ẹṣẹ bibeli ti o wa loke yi, Ọlọrun ko si lara awọn ti a le gan tabi tan jẹ. Nkan ti a ba ṣe ni a o gba ere rẹ lọwọ rẹ. Irugbin ti a ba fun ni Ọlọrun yoo fi ibukun ati ere sori rẹ. Ti a funrugbin nipa ti ara, ni ibamu pẹlu ifẹ inu wa, ninu rikiṣi, ọtẹ, itanjẹ ati ikunsinu, eso ti ara ti o jẹ idibajẹ naa ni a o ka. Ti a ba si funrugbin nipa ti Ẹmi, ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun bi a ti ṣe la a kalẹ ninu iwe mimọ, eso ti Ẹmi ti a o ma gbadun titi ayeraye naa ni a o ka.
O wa ku sọwọ wa irufẹ irugbin ti a fẹ fun ati bi a ti ṣe fẹ fun. Amọ iyanju Pọọlu si wa ni pe ki a ma ṣe jẹ ki agara da wa ni rere ṣiṣe si gbogbo eniyan, paapaa julọ awọn ti o jẹ ọmọ Ọlọrun. Dipo bẹẹ, ki a ma ṣe amulo gbogbo anfaani ti Ọlọrun ba fun wa lati fifunni ati lati fifunni ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ. Ki si ni idi? Idi ni pe ni akoko ti o tọ, Ọlọrun yoo pin wa lere. Ọlọrun nikan ni O mọ akoko ti o tọ fun ere ohun rere yowu ti a ba ṣe. Oun nikan naa si tun ni O mọ irufẹ ere ti o tọ si wa laye yi ati ninu ijọba ayeraye rẹ. Ko wa yẹ ki a ma ṣe oore ni ireti pe ọna kan pato ni Ọlọrun gbọdọ gba lati san wa lẹsan rẹ. Ifurugbin nipa ti ara ni eyi jasi. O si ṣeeṣe ki a ma ri nkankan gba lori rẹ.
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Ọmọ Ọlọrun kọọkan gbọdọ mura lati gbe ẹru rẹ dipo eyi ti yoo fi sọ ara rẹ di bukata fun awọn ara rẹ ninu Kirisiti. Sibẹsibẹ, ifẹ Ọlọrun ni fun wa lati ma ran awọn ara wa lọwọ lati gbe ẹru aye wọn ati lati rin irinajo igbagbọ wọn ni pipe. Ọna ti a wa n gba ṣe eleyi ṣe pataki pupọ si Ọlọrun. A si nilo lati mọ ọn, ki a si tun tẹle. Aijẹbẹ, a ko ni ri ere kankan gba fun ohun rere yowu ti a ba ṣe.
ÌBÉÈRÈ
- Ọna pataki wo ni Pọọlu sọ ninu ẹkọ yi pe a le gba lati dena iṣubu awọn ara wa ninu Kirisiti?
- Ki ni o ṣe pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi?
Lati ọwọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2023 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07025105978)