August 2021

Orisun rẹ jẹ ẹ loogun pẹlu | Paitọ J.O. Lawal

Ọjọ: Ogun 29, 2021 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 17

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo ki a kaabọ si ọjọ isinmi ti o kẹyin oṣu Ogun 2021. Mo si gbadura pe ki Oluwa ṣe ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu ọrọ aye rẹ ninu oṣu naa ni aṣepe, ni orukọ Jesu. Amin.

Ni aipẹ yi, mo ni itakurọsọ pẹlu ọdọmọbinrin kan ti ọkan rẹ n poruru nitori eto iṣuna ile rẹ ati nitori pe nkan ko lọ deede fun wọn gẹgẹ bi wọn ṣe fẹ. Bi o si ṣe sọ fun mi, ọkan rẹ poruru lori ọrọ yi to bẹẹ gẹẹ ti o fi bẹrẹ si ni ronu ni akoko kan lati di ‘Ọmọ yahuu.’ A si wa mọ pe awọn ti a n pe ni ‘Ọmọ yahuu’ yi ko yatọ si gbajuẹ ati ole. Yatọ si pe gbajuẹ ati ole ni wọn, wọn tun jẹ aṣeṣo. Eyi tunmọ si pe ọpọ wọn, ti ko ba tilẹ jẹ gbogbo wọn, ni wọn ni nkan kan tabi omiran ni i ṣe pẹlu awọn iwin tabi ẹmi aimọ lati ni owo. Ti wọn ko ba si ronupiwada, o di dandan ki wọn parun ki aye wọn gan an to bẹrẹ.

Ṣugbọn ki wa lo fa a ti arabinrin yi fi ronu lati da ‘Ọmọ yahoo’? Ibeere ti mo si bere lọwọ rẹ gan an niyi. Mo ni, “Kirisitiani ni ọ, eyi ti o si ni iṣẹ lọwọ. Ki lo wa fa a ti o fi gbero lati ṣe iru nkan yi?” Idahun rẹ si jọ ni loju diẹ. O jọ ni loju nitoripe, gẹgẹ bi o ti ṣe wi, o ti ṣe alabapade awọn ‘Ọmọ Yahuu’ ninu ipade sọọsi lọpọ, o si n wo bi wọn ṣe n nawo ninu awọn ipade yi ati bi awọn kan ti a n pe ni adari ijọ ṣe n yin wọn, pọn wọn le ati gbadura fun wọn. Eyi si jẹ ki o ni ero pe wọn n ṣe fọrifọri fun oun ati pe oun ati ọkọ oun naa nilo lati ṣe nkankan lori eto isuna wọn.

A wa dupẹ lọwọ Ọlọrun nitoripe, bi o tilẹ jẹ pe arabinrin yi gbero lati tọwọ bọ iṣẹ ibi yi, Ẹmi Mimọ ko gba fun. Ṣugbọn koko ọrọ gan ni pe ọpọ ni o wa ninu sọọsi loni ti wọn n ṣe oniruuru iṣẹ ti ko ba ofin mu, ti ara wọn si balẹ laarin wa nitoripe ko si ẹni ti o n ba wọn wi tabi kilọ fun wọn. Bi o si ti wa wu ki wọn fi fun sọọsi to tabi ki awọn kan kọrin yin wọn to, iṣẹ wọn ati ọrẹ wọn jẹ irira si Ọlọrun.

Nitorina, yatọ si pe wọn ko ni ri ere kankan gba lọwọ rẹ fun nkan ti wọn n ṣe, Oun yoo tun ba wọn wi ni akoko ti ọ tọ fun awọn iṣẹ ibi ti wọn n ṣe ati fun igboya ti wọn ni lati ro pe awọn le fun Ọlọrun ni abẹtẹlẹ pẹlu ere iwa ika. Ni abẹ majẹmu atijọ, Ọlọrun sọ fun awọn eniyan rẹ pe, “Ki agbere ki o ma ṣe si ninu awọn ọbinrin Isirẹli, tabi oniwa Sodomu ninu awọn ọmọkunrin Isiraẹli. Iwọ ko gbọdọ mu owo ọya agbere, tabi owo aja, wa sinu ile Oluwa Ọlọrun rẹ fun ẹjẹkẹjẹẹ: nitori pe irira ni ani awọn mejeeji si Oluwa Ọlọrun rẹ.” (Ditaronomi 23:17-18)

Njẹ o ri bayi? Nkan ti a n ṣẹ fun ounjẹ oojọ wa jẹ Ọlọrun logun. Ọna ti owo n gba wọle si wa lọwọ jẹ ẹ logun. Ti a ba si n ṣe ohun ti O korira, ki a ya ma mu owo tabi ọrẹ wa fun lati ipasẹ rẹ. Idi si ni pe bi eniyan ko ba mọ nkan ti a n dan an wo, Oun mọ nkan ti a n dan an wo, yoo si pin wa lere bi o ṣe tọ ati bi o ṣe yẹ. Si wa wo o, ko ki i ṣe awa nikan ni yoo da jẹ iya radarada ti a n ṣe yi; gbogbo awọn adari ijọ ti o n ki wa laya tabi ran wa lọwọ lati ṣe e naa yoo ba wa nipin ninu ijiya naa lọna ti o ga.

Ki ni idi ti Ọlọrun fi papa pa Balaamu ariran run? Idi ni wipe o fẹran ere iṣẹ ibi. O jẹ ọkunrin kan ti o ṣetan lati sọtẹlẹ fun ẹnikẹni, gbadura fun ẹnikẹni tabi fi ẹnikẹni gegun ti a ba fun ni owo ti o to owo, lalai wadi nkan ti irufẹ ẹni bẹ gan n ṣe. Nitorina, Ọlọrun pa a run, gẹgẹ bi o ṣe di dandan fun un lati pa gbogbo awọn oniwaasu ti wọn n tọ isisẹ rẹ arun pẹlu, ti awọn naa ba fi akoko ṣofo lati ronupiwada. (Wo: Numeri 22-24 & 31:8)

Nitorina, ma fi gbogbo igba ranti pe bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun fẹ ki a lawọ si Oun, ibi ti awọn nkan ti a n fun un ti n wa jẹ ẹ logun pẹlu. Idi si ni yi ti o ko gbọdọ lọwọ si ohun aimọ kankan tabi ki o gba ki ẹnikẹni ti ọ lati lọwọ si (Efesu 4:28). Aijẹbẹ, nṣe ni o o kan ma fi gbogbo nkan ti o n fun Ọlọrun tabi sọọsi ṣofọ — iparun rẹ ko si ni sun lọ.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Orisun rẹ jẹ ẹ loogun pẹlu | Paitọ J.O. Lawal Read More »

Ohun buburu kan | Paitọ J.O. Lawa

Ọjọ: Ogun 22, 2021 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 16

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lẹkunrẹrẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọṣẹ tuntun miran ninu oṣu Ogun 2021. Adura mi si ni pe ki Ẹmi Ọlọrun ma fi gbogbo igba di ọ lọwọ lati ma fẹ tabi ṣe ohun kankan ti yoo ṣi aye silẹ fun idajọ Ọlọrun lati wa si ori rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, adura yi le ma fi taratara dabi adura kan to nipọn tabi loorin loju ọpọlọpọ. Ṣugbọn Pọọlu gba iru rẹ fun awọn ara Kọrinnti nigba ti o sọ bayi, “Njẹ awa n gbadura si Ọlọrun ki ẹyin ki o ma ṣe ṣe ohun buburu kan…” (2Korinnti 13:7) Nitorina, bi o tilẹ jẹ wipe adura yi dabi ọkan ti ko lowura lọtiti, adura ti o ba ọrọ iwe mimọ mu ni gbogbo ọna ni. Niwọn igba ti o si ti ba ọrọ iwe mimọ mu, gbigba rẹ le jasi iyatọ laarin iye ati iku tabi laarin igbesoke ati ijakulẹ fun wa.

Fun apẹẹrẹ, Rubẹni ko gba egun baba rẹ nitoripe o jẹ ọdọmọkunrin onijagidijagan kan, ẹni ti o ma n fi gbogbo igba da wahala ati irora silẹ. Dipo eyi, o gba egun sori rẹ nitori nkan buburu ẹyọkan ṣoṣo ti o ṣe. O ba iyawo baba rẹ lopọ. Idi ti o ṣe ṣe eleyi ni a ko sọ fun wa ninu bibeli. Boya nṣe ni arabinrin yi tilẹ fi arekereke mu, bi aya Potifa naa ṣe fẹ fi arekereke mu Josefu. A ko mọ. Ṣugbọn ẹṣẹ ẹyọkan ṣoṣo yi jẹ ki oun ati awọn arọmọdọmọ rẹ sọ aye titayọ wọn nu ninu aye yi. (Wo: Jẹnẹsisi 35:21-22 & 43:3-4)

Lafikun, ki ni o pa Nadabu ati Abihu, meji ninu awọn ọmọ Aaroni, ni ọjọ kanna ati ni akoko kanna? Igbesẹ odi kan ṣoṣo ti wọn ma gbe ni. Eniyan daadaa si ni wọn o. Yatọ si eyi, alufa ti Ọlọrun fi amin ororo yan tun ni wọn pẹlu. Amọ nigba ti wọn fi ajeji ina rubọ niwaju Ọlọrun, ina ti ọdọ rẹ jade si wọn, o si jo awọn mejiji run lẹsẹkẹsẹ. A ko tilẹ fun wọn ni ikilọ tabi aye ati ronupiwada. Nitorina, nkan buburu ẹyọkan bayi le ṣi ilẹkun aye wa silẹ fun idajọ kiakia tabi fun ọjọ aye ti o fi ojoojumọ kun fun iyọnu. (Wo: Lẹfitiku 10:1-2)

Wo o, awọn eniyan le ma ṣe oniruuru nkan ti ko dara, ki a si ma jẹ wọn niya lẹsẹkẹsẹ tabi ni ọna kan ti o lagbara tabi ti o ṣe fojuri. Ṣugbọn ti wọn ba kan lọ gbe igbesẹ aidara kan si, eyi ti o tilẹ le ma dabi ẹni ti o buru to ti awọn eyi ti wọn ti n gbe tẹlẹ, wọn le ba ara wọn ninu babanla iyọnu pẹlu Ọlọrun. Nkan ti o ṣẹlẹ si ọba Bẹliṣasari ni eyi. Ọlọrun ko lu pa tabi gba ijọba lọwọ rẹ fun ọkankan lara gbogbo awọn nkan buruku ti o ti n ṣe ki o to di ọjọ ti oun ati awọn eniyan rẹ woye pe ki awọn lo awọn nkan iṣura tẹmpili Ọlọrun fun awẹjẹwẹmu wọn. Ṣugbọn lọjọ ti o ṣe eyi, a paṣẹ idajọ iku fun. A si pa a, a si tun fa ijọba rẹ le ẹlomiran lọwọ. (Wo: Daniẹli 5)

Nibakanna, eniyan le ti ma ṣe ohun gbogbo daradara niwaju Ọlọrun, ki o si ma gba oriyin lati ọdọ rẹ. Ṣugbọn iwa aidara kan ti o ba wu bayi le jẹ ki o padanu ẹmi rẹ, iṣẹ iranṣẹ rẹ tabi aye rẹ ninu ijọba Ọlọrun. Ranti Mose. Iwa aida ẹyọkan pere naa lo wu ti o si padanu iṣẹ iranṣẹ didari awọn ọmọ Isiraẹli wọ ilẹ ileri. Nitorina, nkan buburu kan le ba ohun gbogbo jẹ fun wa. (Wo: Numeri 20:1-13)

Idi niyi ti mo si fi ri adura Pọọlu fun awọn ara Kọrinnti gẹgẹ bi eyi ti o ṣe pataki pupọ si mi ati pẹlupẹlu si gbogbo ọmọ Ọlọrun. Ki si ni adura naa? Ohun na ni pe ki a ṣọ wa lati ma ṣe ṣe ohun aidara kankan, boya eyi ti yoo yọri si iku fun wa ni o tabi eyi ti yoo yọri si ijakulẹ, iparun, ibanujẹ tabi igbe aye radarada fun wa, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ohun buburu kan | Paitọ J.O. Lawa Read More »

Má sọ ààyè rẹ nù

Idajọ ẹtan | Paitọ J.O. Lawal

Ọjọ: Ogun 15, 2021 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 15

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ pipọsi fun ọ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ogun 2021. Adura mi si ni pe ki ọkan rẹ ma fi gbogbo igba gba okun lati ọdọ Ẹmi Ọlọrun lati rin ninu ifẹ ati otitọ inu pẹlu awọn eniyan Ọlọrun ti o wa ninu aye rẹ, ki o ma ba ṣilẹkun aye rẹ silẹ fun idajọ Ọlọrun dipo ki o ma gbadun ẹkunrẹrẹ ayọ ibaṣepọ Kirisitiẹni si Kirisitiẹni. Amin.

Bibeli sọ wipe, “Ẹ ma si ṣe purọ fun ẹnikeji yin, ẹyin sa ti bọ ogbologbo ara ẹṣẹ ni silẹ ati iṣẹ buburu rẹ; Ẹ si ti gbe ara tuntun ni wọ, eyi ti a sọ di tuntun gẹgẹ bi aworan ẹni ti o da a, sinu imọ kikun.” (Koloso 3:9-10) Njẹ o ri bayi? Irọ pipa, eke ṣiṣe tabi ẹtan jẹ ọmọ iṣẹda iku ti Ọlọrun yọ danu kuro ni aye wa nigba ti a di atunbi. Nitorina, a ko gbọdọ gba a laye ninu aye wa tabi ninu ibaṣepọ wa pẹlu ara wa. Aijẹbẹ, a o ma ṣilẹkun aye wa silẹ fun idajọ Ọlọrun. Tani o si mọ ọna ti O le gba dawa lẹjọ? Ko si!

Fun apẹẹrẹ, ti Ananaya ati Safira iyawo rẹ ba lero pe Ọlọrun le fun wọn ni idajọ iku lori pe wọn fi ẹtan ba awọn awọn eniyan rẹ lo pọ ni, o ṣeeṣe ki wọn ma ṣe bi wọn ṣe ṣe nigba yẹn. Ṣugbọn nitori pe wọn ko ni lọkan rara pe O le e ṣe bẹ, wọn parọ nipa fi fifunni wọn, a si da seria fun wọn lẹsẹkẹsẹ. Awọn mejeeji si ni Ọlọrun da lẹjọ, ti O si tun pa ni ọjọ kannaa. (Wo: Iṣe Apọsiteli 5:1-11)

Wayi o, ẹnikan wa le sọ wipe, “Ṣebi ọpọ laarin awọn ọmọ Ọlọrun lo si ma n wuwa ẹlẹtan loorekoore. Sibẹsibẹ, ko ki i ṣe gbogbo igba ti wọn ba ṣe eleyi ni Ọlọrun n lu wọn pa. Ki lo wa fa ti ọrọ ti Ananaya ati ti iyawo rẹ ṣe yatọ niwaju rẹ?” Lakọkọ, a gbọdọ jẹ ki o ye wa pe wipe Ọlọrun ko ṣe idajọ iku fun awọn eniyan lẹsẹkẹsẹ nitori pe wọn wuwa ẹtan tabi ṣe nkan buburu miran ko tunmọ si pe ko ma ṣe idajọ fun wọn rara. O ni ọpọ ọna ti O fi n ṣe idajọ awọn eniyan. Ti wọn ko ba si ni ifura, wọn le ma fi akoko kankan mọ pe a n ṣe idajọ wọn.

Ekeji, a nilo lati jẹ ki o ye wa pe ko ki i ṣe pe Ọlọrun fi ojusaaju bọ ọrọ Ananaya ati iyawo rẹ. Nkan ti o ṣẹlẹ ni pe O kan pinnu lati fi wọn jofin ni, ki wọn ba le jẹ arikọgbọn fun awọn miran ti wọn le fẹ ma rin nipasẹ wọn. Adura mi si ni pe o ko ni gbe igbesẹ kankan ti yoo jẹ ki Ọlọrun fi ọ se arikọngbọn ọna ti O n gba ṣe idajọ ibi fun awọn eniyan. Amin. Ṣugbọn ki gan an lo fa ti Ọlọrun fi lo Ananaya ati Safira gẹgẹ bi arikọgbọn fun awọn miran? Idi ni wipe wọn gbiyanju lati fi ẹtan lọlẹ ninu ijọ rẹ. Awa naa si gbọdọ kiyesara lori irufẹ awọn nkan ti a n filọlẹ ninu ijọ Ọlọrun, nitori pe O n wo wa, yoo si pin wa lere gẹgẹ bi iṣẹ ọwọ wa ba ṣe ri.

Ni kukuru, bi akọsilẹ bibeli ṣe fi ye wa, nkan ti o ṣẹlẹ si Ananaya ati aya rẹ ṣẹlẹ ni akoko ti ifẹ Kirisiti n jọba lotitọ ninu aye awọn eniyan rẹ ati lori ọrọ aye wọn. Ifẹ yi si gbakoso aye wọn to bẹẹ gẹẹ ti awọn ti wọn ni awọn nkan ini to lowura bẹrẹ si ni ta wọn, ti wọn si n mu owo ti wọn pa nibẹ wa fun awọn apọsiteli lati pin fun awọn ti o ṣe alaini ni aarin wọn. Eyi gan an lo le iṣẹ jade kuro laarin wọn, nitoripe bibeli sọ wipe, “Ko si alaini kankan ni aarin wọn ni akoko yi.” (Wo: Iṣe Apọsiteli 4:32-35)

Nitorina, gbogbo awọn ara ni akoko yi, iye yowu ti wọn jẹ, ni wọn n ba ara wọn lo pẹlu otitọ ati ifẹ. Bi Ọlọrun si ṣe fẹ ki o ri ni eyi, nitoripe eyi ni yoo jẹ ki awọn ti aye yi mọ pe ọmọlẹyin Kirisiti Jesu Oluwa ni wọn nitootọ. O wa ṣe ni laanu pe, ni akoko kannaa yi, Satani ṣe aṣeyọri lati mu ki Ananaya ati iyawo rẹ bẹrẹ si ni ronu yatọ ati wuwa yatọ. Bi wọn ṣe pẹ to lori eleyi ni a ko mọ. Ṣugbọn a mọ pe, ni akoko kan, awọn naa, gẹgẹ bi awọn ara yoku, ṣeleri lati ta ilẹ wọn kan ati lati mu owo rẹ wa sinu ijọ. Wọn si ṣe bẹẹ gẹgẹ.

Amọ ṣa o, wọn ko ṣetan lati mu gbogbo owo ti wọn pa nidi ilẹ ti wọn ta naa wa siwaju Ọlọrun. Nitori naa, wọn fi diẹ lara rẹ pamọ fun ara wọn. Njẹ eyi jẹ nkan ti o buru bi? Rara o! Awọn ni o ni owo yi lakọkọ, bi Peteru ṣe sọ fun wọn lẹyinọrẹyin. Nitori naa, wọn ni aṣẹ lati sọ bi wọn ṣe fẹ ẹ lo o. Ṣugbọn lati wa gbiyanju lati tan awọn eniyan Ọlọrun yoku jẹ, awọn eniyan rẹ ti wọn nifẹ wọn, ti ọrọ aye wọn si jẹ wọn logun, ki wọn si jẹ ki o dabi ẹni pe owo ti wọn fi silẹ ju iye ti wọn fi silẹ lọ jẹ eyi ti ko ṣe itẹwọgba ni ọwọ Ọlọrun. Idi niyi ti O ṣe ṣe idajọ ẹtan wọn, ti O si lo eyi lati fun awọn miran bi tiwọn ni anfaani lati kẹkọ ati lati ronupiwada.

Ni bakanna, ti awa naa ko ba ni rin pẹlu ifẹ ati ọkan otitọ pẹlu awọn ara wa ninu oluwa, boya nipa awọn ọna ti a n gba lo nkan ini wa tabi ẹbun ẹmi wa ni tabi nipa awọn ọna ti a n gba ṣe awọn nkan miran, a le ma ṣi ilẹkun silẹ fun idajọ Ọlọrun, eyi ti o si le ja si iku ti ara. Nitorina, ẹ jẹ ki a fi aye gba ọrọ Ọlọrun lati fọ wa mọ kuro ninu aiṣododo ati agabagebe gbogbo, nigba ti eyi si ṣeeṣe. Ki Ẹmi Ọlọrun si ran iwọ ati emi lọwọ lati ṣe ohun ti o tọ lori ọrọ yi, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ adun o.

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Idajọ ẹtan | Paitọ J.O. Lawal Read More »

ALAYTHIA BIBLE CHURCH (IJỌ OTITỌ BIBELI)
ALAKALẸ ẸKỌ BIBELI ATI ALAYE
ỌJỌRU 11, OGUN 2021

AKỌRI: PASITỌ AYỌKA: JOHANU 21:15-17

AKỌSORI: AKỌSORI: “Ẹ kiyesara yin, ati si gbogbo agbo ti Ẹmi Mimọ fi yin ṣe alabojuto rẹ, lati maa bọ ijọ Ọlọrun, ti o fi ẹjẹ rẹ ra.” (Iṣe Awọn Apositeli 20:28)

ỌRỌ AKỌSỌ
Ninu lẹta rẹ si awọn ara Efesu, apọsiteli Pọọlu sọ eyi nipa Jesu: “O si ti fi awọn kan fun ni bii apọsiteli; ati awọn miiran bii wolii ati awọn miiran bii ẹfanjẹlisiti ati wọn miiran bii olusọ-aguntan ati olukọni; Lati pese awọn eniyan mimọ silẹ fun iṣẹ iranṣẹ, fun imudagba ijọ, ti i ṣe ara Kirisiti.” (Efesu 4:11-12) Pẹlu nkan ti o sọ yi, kedere ni a ri pe lara awọn ti Jesu Oluwa wa funrarẹ yan fun ijọ awọn eniyan rẹ fun imuyẹ fun iṣẹ iranṣẹ ati fun idagbasoke wọn ni a ti ri awọn ti a n pe ni oluṣọ-aguntan ati olukọni. Awọn wọnyi naa si ni ọpọ mọ si pasitọ loni. Awọn wo gan wa ni a le pe ni pasitọ? Ki ni awọn amuyẹ ti a n i lati ri ninu eniyan ki a to le tọka si gẹgẹ bi pasitọ? Ki ni ojuṣe pasitọ? Njẹ iṣẹ iranṣẹ rẹ ni aala bi? Iha wo ni o yẹ ki ijọ Ọlọrun kọ si awọn pasitọ wọn? Wọnyi ni awọn ibeere ti a o ma tipasẹ ẹko yi ti o da lori iṣẹ iranṣẹ pasitọ dahun. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun lo ẹkọ naa lati wẹ aimọkan yowu ti a ba ni lori iṣẹ iranṣẹ pasitọ danu kuro ninu aye wa, ki a ba le ma ba awọn pasitọ ijọ wa lo ni ọna ti o yẹ ati ki awa yowu ti a jẹ pasitọ naa le mu iṣẹ iranṣẹ wa lọkunkundun, ki a si tun ṣe atunṣe nibi ti o ba ti yẹ. Amin.

TANI PASITỌ?
Ọpọ loni ni a n pe ni pasitọ ti wọn ko si ki i ṣe pasitọ rara – inagijẹ laṣan ni apẹle yi jẹ fun wọn. A n pe awọn kan ni pasitọ nitoripe wọn ma n fi gbogbo igba gbe bibeli kaakiri tabi waasu si awọn ti o wa ni ayika wọn. A si n pe awọn miran ni pasitọ nitoripe wọn ti lọ si ile-ẹkọ bibeli kan tabi omiran, ti wọn si n wọ aṣọ ẹgbẹjọda onikọla ati ti wọn si wa lori ijọ Ọlọrun kan tabi omiran gẹgẹ bi adari. Awọn miran ẹwẹ ni a n pe ni pasitọ nitori iṣedeede wọn ninu ijọ wọn. Sugbọn eniyan ko ki i ṣe pasitọ tabi olusọ-aguntan nitori awọn nkan wọnyi. Eniyan jẹ pasitọ nitori pe Ọlọrun yan an, O si tun fun ni awọn ẹbun Ẹmi Mimọ ti o ṣe pataki lati duro gẹgẹ bi olusọ-aguntan ati olukọni fun awọn ọmọ rẹ.

Nkan ti a n sọ ni wipe, gẹgẹ bi Pọọlu ṣe fi ye wa ninu lẹta rẹ si awọn ara Efesu ti o wa loke, pasitọ jẹ ẹnikan ti Jesu Oluwa wa yan, ti O si tun ṣe yẹ lati jẹ oluṣọ-aguntan, alabojuto ati olukọni fun awọn ọmọ Ọlọrun. Fun apẹẹrẹ, lẹyin ajinde rẹ, Jesu fi ara han diẹ lara awọn ọmọ ẹyin rẹ lọjọ kan, a si kọ eyi silẹ nipa nkan ti O sọ fun Peteru:

“Lẹyin igba ti wọn jẹun owurọ tan, Jesu wi fun Simoni Peteru pe, Simoni, ọmọ Jona, iwọ fẹ mi ju awọn wọnyi lọ bi? O si wi fun un pe, Oluwa; Iwọ mọ pe mo fẹran rẹ, O wi fun un pe, Maa bọ awọn ọdọ-agutan mi. O tun wi fun un nigba keji pe, Simoni, ọmọ Jona, iwọ fẹ mi bi? O wi fun un pe, Bẹẹ Oluwa; iwọ mọ pe mo fẹran rẹ. O wi fun un pe, Maa bọ awọn agutan mi. O wi fun un nigba kẹta pe, Simoni, ọmọ Jona, iwọ fẹran mi bi? Inu Peteru bajẹ, nitori ti o wi fun un nigba ẹkẹta pe, Iwọ fẹran mi bi? O si wi fun un pe, Oluwa, iwọ mọ ohun gbogbo; iwọ mọ pe, mo fẹran rẹ. Jesu wi fun un pe, Maa bọ awọn agutan mi.” (Johanu 21:1l5-17)

Bi a ti ṣe ri ninu awọn ẹsẹ bibeli yi, Jesu funrarẹ ni O yan Peteru lati ṣe amujoto awọn aguntan rẹ. Oun ko wa ni yan ẹnikẹni lati ṣe ohunkohun ti ko ba ṣetan lati mu ẹni naa yẹ lati ṣe e. Nitori eyi, nipa sisọ fun Peteru lati bọ tabi tọju awọn aguntan rẹ, o tunmọ si pe O ti pinnu lọkan rẹ lati ṣe arakunrin yi yẹ fun iṣẹ naa niyẹn. Awọn wo wa ni aguntan rẹ ti O n tọka si nigba ti O n ba Peteru sọrọ? Gbogbo ijọ awọn ti o gbagbọ ninu rẹ, awọn eniyan mimọ rẹ, ni aguntan rẹ. (Cf. Luuku 12:32; Johanu 10:1-16)

Ni kukuru, pasitọ jẹ ẹni kan ti Jesu yan, ti O si mu yẹ lati ṣe amujoto awọn ọmọlẹyin rẹ nibi yowu ti wọn le wa ati iye yowu ti wọn le jẹ, ki ifẹ rẹ ba le wa si imuṣẹ ninu aye wọn. Iru awọn ẹni bẹẹ ni a si tun tọka si ninu bibeli gẹgẹbi alagba tabi biṣọọbu. Boya wọn wa jẹ pasitọ lori ijọ Ọlọrun kekere tabi pupọ kọ ni koko. Koko ni pe Jesu yan wọn, O si ṣe wọn yẹ lati ṣe amojuto awọn ọmọ rẹ. (Wo: Iṣe Apọsiteli 19:1-7; 1Timoti 1:3; Titu 1:5)

KI NI AWỌN AMUYẸ PASITỌ?
Ki wa ni awọn nkan ti o gbọdọ wa ninu eniyan ki a to le ri gẹgẹ bi ẹnikan ti Jesu ti yan lati jẹ pasitọ tabi oluṣọ-agutan fun awọn ọmọ rẹ? Pọọlu mẹnuba pataki lara awọn nkan wọnyi ninu lẹta rẹ akọkọ si Timoti, eyi ti o ka bayi:
“Otitọ ni ọrọ naa, bi ẹnikan ba fẹ lati jẹ biṣọọbu, iṣẹ rere ni o n fẹ. Nitori bisọọbu gbọdọ jẹ alailẹgan, alaya kan, ẹni ti o lee ko ara rẹ ni ijanu, ẹni ti n fi ọgbọn ṣe ohun gbogbo, olorukọ rere, olufẹ alejo ṣiṣe, ẹni ti o ni oore-ọfẹ lati kọ awọn eniyan. Ẹni ti kii ṣe omuti, tabi oniwahala, bi ko ṣe onisuuru, kii ṣe onija, tabi olufẹ owo; Ẹni ti o lee ṣe akoso idile rẹ daradara, ti awọn ọmọ rẹ si le gbọ tirẹ pẹlu itẹriba ni ohun gbogbo; (Nitori bi ọkunrin kan ko ba mo bi oun o ti ṣe ikawọ idile ara rẹ, oun o ha ti ṣe le tọju ijọ Ọlọrun?) Ki o ma ṣe jẹ ẹni tuntun ninu igbagbọ, ki o ma baa gberega, ki o si ṣubu gẹgẹ bi Eṣu ti ṣe. O si yẹ ki o ni ẹri rere pẹlu lọdọ awọn alaigbagbọ: ki o ma baa bọ sinu ẹgan ati sinu idẹkun Eṣu.” (1Timoti 3:1-7)

Bi mo ti ṣe sọ siwaju, ni igba aye awọn apositeli Pọọlu, ara awọn apele ti a tun le lo fun pasitọ tabi oluṣọ-aguntan ni biṣọọbu tabi alagba. Nitorina, awọn amuyẹ ti Pọọlu sọ pe eniyan gbọdọ ni ki Timoti to le fi ṣe biṣọọbu tabi alamojuto fun awọn ọmọ Ọlọrun naa ni pasitọ gbọdọ ni. Lotitọ Ọlọrun nikan naa ni o le yan eniyan, ki O si tun ṣe yẹ lati jẹ pasitọ. Amọ ko digba ti Ọlọrun ba kọ si wa lati ọrun pe pasitọ ni ẹnikan ki a to mọ boya pasitọ ni tabi pasitọ kọ. Ti a ba ti kiyesi awọn amuyẹ ti Pọọlu sọrọ nipa wọn ninu awọn ẹṣẹ bibeli ti o wa loke yi ninu aye eniyan, a le sọ daju boya a ṣe e yẹ lati jẹ pasitọ tabi bẹẹ kọ.

Gẹgẹ bi a si ti ṣe ri, awọn amuyẹ naa ko ni nkankan ṣe pẹlu pe ki a lọ si ile ẹkọ bibeli tabi ki a so kọla funfun mọ ọrun tabi ki a de ade biṣọọbu. Dipo eyi, lakọkọ, wọn ni i ṣe pẹlu ki eniyan jẹ ọmọ Ọlọrun ti aye rẹ n ti n so eso ẹmi fun akoko ti o kojuosuwọn, ti a si le jẹri nipa rẹ. Ki si ni idi? Idi ni wipe pataki iṣẹ pasitọ ni ki o ṣe amojuto awọn ọmọ Ọlọrun lati jẹ ki aye wọn ri bi Ọlọrun ṣe fẹ ki wọn ri. Ti aye tirẹ gan ko ba wa jẹ apẹẹrẹ nkan ti Ọlọrun fẹ ri ninu aye awọn ọmọ rẹ, ti oun funrarẹ ko ma so eso ẹmi fun igba ti o ṣe diẹ to lati jẹ ki awọn eniyan mọ pe dajudaju ọmọ Ọlọrun tootọ ni o jẹ, bawo ni o ṣe le jẹ pasitọ tootọ ati rere?

Ekeji, awọn amuyẹ ti Pọọlu n sọrọ nipa ni i ṣe pẹlu ki eniyan ni ẹbun ẹmi lati kọ ọrọ Ọlọrun. Gẹgẹ bi a si tun ṣe ri ninu lẹta rẹ si awọn ara Efesu, akopọ ni Jesu fi iṣẹ pasitọ ati olukọni ṣe. Idi si ni pe ko si bi eniyan ṣe fẹ jẹ pasitọ to dangajia ti ko ba le kọ awọn eniyan ni ọrọ Ọlọrun. Bawo ni o ṣe fẹ fi ifẹ Ọlọrun han si awọn ti o n ṣedari, ti ko ba le kọ wọn ni ọna ti o ye kooro? Nitorina, ẹnikẹni to ko ba le fi arabalẹ kọ awọn eniyan ni ọrọ Ọlọrun pẹlu suuru ati lẹsẹẹsẹ ko ki i ṣe pasitọ, bi o tilẹ n wọ kọla tabi bi o tilẹ ti lọ si ile-ẹkọ bibeli kan tabi omiran.

Wayi o, ẹni ti yo wa kọ eniyan ni ọrọ Ọlọrun naa gbọdọ mọ Ọlọrun ati ọrọ rẹ daju. O gbọdọ ni oye gbogbo ifihan Ọlọrun ti o wa ninu bibeli ati bi awọn ifihan yi ṣe gbọdọ tọ iṣiṣẹ aye awọn eniyan. Bẹẹni o gbọdọ le sọ daju bi Pọọlu ṣe sọ fun awọn alagba ijọ Efesu pe, “Emi ko fa sẹyin lati sọ ohunkohun ti o le ṣanfani fun yin ati lati sọ gbogbo ipinnu Ọlọrun fun yin.” (Wo: Iṣe Apositeli 20:20&27) Aijẹbẹ, a ko le pe ni ẹni amuyẹ fun iṣẹ pasitọ. Idi ni yi ti a fi ni awọn eke pasitọ ati olukọ. Awọn wọnyi ni awọn apositeli igbaani kilọ fun wa lati kiyesara fun. Ko si soro lati mọ wọn. Idi ni si pe eso ti aye wọn n so yoo fi wọn han. Yatọ si pe wọn yoo jẹ ẹlẹkọ odi, ẹni ti o n tẹle ẹkọ awọn ẹmi eṣu, wọn o tun jẹ opurọ, oniṣẹkuṣe ati ẹni ti aye rẹ ko wa ni ibamu pẹlu ọrọ Ọlọrun ti o ye kooro. Awọn wọnyi ni a gbọdọ yẹra fun, ki wọn ma ba a ṣi wa lọna, ki wọn si gba igbagbọ wa danu kuro lọwọ wa. (Wo: 1Timoti 4:1-5; 2Timoti 4:3; 2Peteru 2; Juudu)

Ẹkẹta, awọn amuyẹ ti Pọọlu n sọrọ nipa ni i ṣe pẹlu ki ẹni ti a n wo bi pasitọ ni ẹbun iṣakoso. Bawo ni a ṣe wa fẹ mọ boya ẹni naa ni ẹbun lati ṣe akoso tabi amojuto awọn ọmọ Ọlọrun? Pọọlu ni ki a wo bi o ṣe n ṣe akoso ile rẹ, gẹgẹ bi ẹni ti o ti gbeyawo, ti o si tun ti bimọ. Ti ko ba wa i ti gbeyawo tabi bi ọmọ nkọ? A le wo bi o ṣe n ṣe akoso awọn ti o wa labẹ rẹ ni bi iṣẹ rẹ tabi ki a dan wo fun igba diẹ pẹlu isakoso awọn eniyan Ọlọrun perete, ki a si wo bi yoo ṣe ṣe si. Nikukuru, a ko gbọdọ kanju fi ẹnikẹni si ipo pasitọ tabi adari ijọ, niwọn igba ti a ko ba i ti ri awọn amuyẹ ti bibeli tọka si ninu aye rẹ. (Wo: 1Timoti 3:10&5:22)

Amuyẹ miran ti a tun nilo lati ri ninu ẹnikẹni ti a le pe ni pasitọ ni ifẹ ati itara lati ṣe amujuto awọn ọmọ Ọlọrun, ki ifẹ rẹ ba a le wa si imuṣẹ ninu aye wọn. Eyi tunmọ si pe pasitọ ko ki i ṣe ẹnikan ti a o ma mu ni ori tabi mu ni ọrun ki o to tara ṣaṣa mu ọrọ awọn ọmọ Ọlọrun ti o wa ni abẹ akoso rẹ ni ọkunkundun. Dipo eyi o jẹ ẹni ti Ọlọrun ti fi ifẹ ati ṣe rere awọn ọmọ rẹ si ni ọkan, ti o si ṣetan lati fi ifẹ yi han ni igba ti o wọ ati igba ti ko wọ. (Wo: Johanu 10:11-13; Roomu 1:11; 2Tẹsalonika 2:17-3:5; 1Peteru 5:2)

KI NI IṢẸ TABI OJUṢE PASITỌ?
Pẹlu awọn nkan ti a ti gbeyẹwo lori amuyẹ pasitọ, ki wa ni awọn nkan ti a le pe ni ojuṣe rẹ? Ki gan ni idi ti Ọlọrun fi n yan pasitọ sori awọn ijọ rẹ? Idi ni pe ko fẹ ki awọn eniyan rẹ dabi aguntan ti ko ni olusọ. Mose, ki o to fi aye silẹ, gba adura yi si Ọlọrun: “Jẹ ki Oluwa, Ọlọrun ẹmi gbogbo eniyan, ki o yan ọkunrin kan sori ijọ. Ti yoo maa ṣaaju wọn jade lọ, ti yoo si maa ṣaaju wọn wole wa, ti yoo si maa sin wọn lọ, ti yoo si maa mu wọn bọ; ki ijọ eniyan Oluwa ki o ma baa dabi agutan ti ko ni olusọ.” (Numeri 27:16-17) Eyi n fi idi rẹ mulẹ fun wa pe a nilo olusọ-aguntan ninu aye wa ati pe a ko le da ṣe akoso aye wa funra wa (Jeremaya 10:23-24). Ẹni kan ṣoṣo ti o ṣi le se akoso aye wa lọna ti a o fi da ẹni ti o yẹ ki a da ninu Jesu Kirisiti. Idi niyi ti O fi pe ara rẹ ni Oluṣọ-aguntan rere ati alakoso ọkan wa (Johanu 10:11; 1Peteru 2:25).

Amọ ṣa o, bi o tilẹ jẹ pe Jesu gan ni olori oluṣọ-aguntan, ko si ni aye lọwọlọwọ bayi pẹlu wa. Ẹmi mimọ rẹ ni o wa pẹlu wa. Nitori eyi ni O ṣe ma n ṣe awọn eniyan bi ti wa yẹ nipasẹ Ẹmi mimọ rẹ lati ṣe lara iṣẹ rẹ gẹgẹ bi pasitọ gbogbo wa. Ki wa ni awọn iṣẹ tabi ojuṣe yi? Koko rẹ naa ni ṣiṣe amojuto awọn ọmọ Ọlọrun ki ete ati ifẹ rẹ ba le wa si imuṣẹ ninu ati lori aye wọn, ki wọn si pari ere ije wọn ninu aye yi si inu ijọba rẹ (Iṣe Aposteli 20:28; Kolose 1:28-29; 1Peteru 5:2). Eyi si ni i ṣe pẹlu awọn nkan wọnyi:

  • Mimojuto aye ara rẹ lati duro ṣinṣin ninu ifẹ Ọlọrun (Iṣe Apositeli 20:28; 1Timoti 4:15-16).
  • Diduro niwaju awọn ọmọ Ọlọrun gẹgẹ bi apẹẹrẹ ifẹ Ọlọrun (1Timoti 4:12; Titu 2:7-8; 1Peteru 5:3).
  • Kikọ awọn ọmọ Ọlọrun ni ife rẹ, ki wọn ba le mọ iyatọ laarin ohun ti o tọ ati eyi to ko tọ (Lẹfitiku 10:8-11; Malaki 2:7; Esikiẹli 44:23; 1Timoti; 2Timoti; Titu).
  • Adura gbigba fun iduro ṣinṣin awọn ọmọ Ọlọrun ninu ifẹ rẹ ati fun aabo kuro lọwọ awọn onigbagbọ eke ati ikẹkun Eṣu (Iṣe Apọsiteli 6:3-4; Kolose 4:12).
  • Ibawi ati itọsọna awọn ọmọ Ọlọrun, ki ijọ rẹ ba le wa ni ilera (1Korinnti 5; 1Timoti 1:3-7; Titu 1:5-16).
  • Imupada awọn ọkan ti o ṣako lọ (Iṣikiẹli 34:1-6; Galatia 6:1).

BAWO NI PASITỌ ṢE YẸ KI O ṢE IṢẸ RẸ?
Wayi o, ọtọ ni ki pasitọ mọ ojuṣe rẹ, ọtọ si ni ki o ṣe e. Ọtọ tun ni ki pasitọ ṣe ojuṣe rẹ, ọtọ tun si ni ki o ṣe ni ọna ti o ba ifẹ Ọlọrun mu. Pọọlu, ninu lẹta rẹ kan si awọn ara Kọrinnti, sọ wipe ki olukuluku ti o n ṣiṣẹ fun Ọlọrun kiyesara lori ọna ti o n gba a ṣe. Ki si ni idi? Idi ni pe ọna ti a ba gba ṣe iṣẹ rẹ ni yoo so boya yoo yọri si mimu ifẹ, ete ati ipinnu rẹ ṣẹ tabi bẹẹkọ. Yatọ si eyi, ọna ti a ba gba ṣe iṣẹ rẹ ni yoo so boya awa funrawa yoo ri ere gba lati ọwọ rẹ tabi bẹẹkọ. (Wo: 1Kọrinnti 3:5-15 & 9:24-27)

Idi si niyi ti Peteru ṣe gba awọn oluṣọ-aguntan ni iyanju pẹlu awọn ọrọ yi: “Awọn alagba ti n bẹ laarin yin ni mo gbaniyanju, emi ẹni ti i ṣe alagba bi ẹyin, ati ẹlẹrii iya Kirisiti, ati alabaapin ninu ogo ti a o fihan: Ẹ maa ṣe oluṣọ-aguntan awọn eniyan ti Ọlọrun fi sabẹ akoso yin, ẹ maa bojuto wọn, ki i ṣe afipaṣe, bi ko ṣe tifẹtifẹ, bẹẹ ni ki i ṣe ọrọ ere ijẹkujẹ, ṣugbọn pẹlu ọkan ti o mura tan. Bẹẹ ni ki i ṣe bi ẹni ti n lo agbara lori ijọ ti n bẹ labẹ akoso yin, ṣugbọn ki ẹ ṣe ara yin ni apẹrẹ fun wọn. Nigba ti olori Oluṣọ-aguntan ba si de, ẹyin o gba ade ogo ti ki i sa.” (1Peteru 5:1-4)

Pẹlu nkan ti Peteru sọ yi, a ri wipe oluṣọ-aguntan lakọkọ gbọdọ mọ pe oun kọ ni o ni awọn ti o wa ni abẹ akoso rẹ – Ọlọrun ni o ni wọn. Nitorinaa, ko gbọdọ lo ipo ati aṣẹ rẹ lati rẹ wọn jẹ tabi ja wọn lole tabi mu wọn ṣubu tabi mu wọn parun. Dipo eyi, o gbọdọ ṣetan lati sin wọn pẹlu itara, tọkantọkan ati tifẹtifẹ. Yatọ si eyi, o gbọdọ fi gbogbo igba duro niwaju wọn gẹgẹ bi apẹẹrẹ nkan ti Ọlọrun fẹ ri ninu aye wọn. Aijẹbẹ, Ọlọrun ko le ti ipasẹ rẹ mu gbogbo ifẹ rẹ ṣẹ ninu aye awọn ọmọ rẹ. Bẹẹ si ni oun naa ko le ri ere gba lọwọ Ọlọrun fun iṣẹ iriju rẹ. (Wo: 2Kọrinnti 10:8&13:10)

Siwaju si, pasitọ gbọdọ gbe ọkan rẹ le Ọlọrun nikan fun amuyẹ ati aṣeyọri rẹ gẹgẹ bi oluṣọ awọn aguntan Ọlọrun. Pọọlu sọ eyi fun wa: “Kii ṣe pe awa to fun ara wa lati ṣiro ohunkohun bi ẹni pe lati ọdọ awa tikarawa; ṣugbọn tito wa ti ọdọ Ọlọrun wa. Ẹni ti o fun wa ni agbara eyi ti o to lati jẹ iranṣẹ majẹmu tuntun naa; kii ṣe ti iwe, bi ko ṣe ti ẹmi: nitori iwe a maa pani, ṣugbọn ẹmi a maa sọni di aaye.” (2Korinnti 3:5-6) Peteru naa tun sọ wipe, “…bi ẹnikẹni ba n ṣe iṣẹ isin, ki o ṣe e bi agbara ti Ọlọrun fi fun un…” (1Peteru 4:11) Eyi tunmọ si pe pasitọ tabi iranṣẹ Ọlọrun kankan ko gbọdọ gboju le ohun miran yatọ si Ọlọrun fun amuyẹ ati aṣeyọri rẹ. Ko gbọdọ gbojule imọ-ijinlẹ rẹ, ẹkọ rẹ, adura gbigba rẹ, ẹkọ bibeli tabi imọ bibeli rẹ, owo, eniyan, ẹgbẹ okunkun ati bẹẹbẹẹ lọ. Aijẹbẹ, yoo kuna gidigidi.

NJẸ IṢẸ IRANṢẸ PASITỌ NI AALA BI?
Ṣe iṣẹ iranṣẹ pasitọ wa ni alaa tabi gbedeke bi tabi ko ni? A bi ki a sọ pe ṣe ti eniyan ba jẹ pasitọ lotitọ, ṣe gbogbo ọmọ Ọlọrun naa ni o jẹ pasitọ fun? Pọọlu sọ eyi fun awọn ara Korinnti: “Ṣugbọn awa ki yoo ṣogo rekọja ara wa, ṣugbọn ero wa ni lati duro ni ala naa, ti Ọlọrun ti pin fun wa, ani lati de ọdọ yin. Nitori awa ko koja aaye wa rara, bi ẹni pe awa ko de ọdọ yin. Nitori awa tilẹ de ọdọ yin pẹlu ninu iyinrere Kirisiti. Awa ko sogo rekọja ala wa, lori iṣẹ elomiran; ṣugbọn awa ni ireti pe, bi igbagbọ yin ti n dagba si, ki ala wa laarin yin pẹlu maa dagba soke si i.” (1Kọrinnti 10:13-15)

Ki ni eyi n fi ye wa? Oun fi ye wa pe boya pasitọ ni wa ni o tabi apositeli tabi ajinhinrere tabi wolii, iṣẹ iranṣẹ ẹnikọọkan wa ni aala, o ni ibi ti Ọlọrun pin fun wa lati ṣe iṣẹ rẹ. Nitorina, ibi ti aala iṣẹ iranṣẹ wa ba de ni o yẹ ki a ti mura lati lo aṣẹ tabi anfaani ti O ba fun wa. A ko lẹtọ lati lo awọn nkan yi lori tabi laarin awọn ọmọ Ọlọrun ti ko ko si abẹ akoso wa. O wa ṣeni laanu pe ọpọ iranṣẹ Ọlọrun ni ko mọ eyi. Nitorinaa, ọpọ igba ni wọn ma n fẹ ki awọn ti ko mọ wọn ri bu ọwọ fun wọn tabi ran iṣẹ iranṣẹ wọn lọwọ tabi tẹlẹ aṣẹ tabi imọran wọn nitoripe wọn jẹ pasitọ, wolii ati bẹẹbẹẹlọ. Nigba ti eyi ko ba si waye, wọn a sọ da ibinu. Eyi si le fa idajọ Ọlọrun wa si ori wọn, bi idajọ rẹ ṣe wa si ori Mose nitoripe ko fi ọwọ Ọlọrun wọ awọn eniyan rẹ ni ọjọ kan. (Wo: Numeri 20:1-12)

Nitori naa, ti o ba jẹ pasitọ, mọ awọn ti Ọlọrun yan ọ gẹgẹ bi pasitọ lori wọn, ki o si jẹ ki lilo aṣẹ rẹ tabi anfaani iṣẹ iranṣẹ rẹ mọ ni aarin wọn. Ti Ọlọrun si ba wa tun jẹ ki alaa iṣẹ iranṣẹ rẹ gbooro si, o tun le tẹsiwaju lati lo aṣẹ ati anfaani iṣẹ iranṣẹ rẹ lati ṣe amojuto awọn miran ti O ba tun fi si abẹ akoso rẹ. Ṣugbọn ma ṣe ṣe aṣiṣe lati ṣakoso aye awọn ti Ọlọrun ko fi si abẹ akoso rẹ. Eyi le ko ba ọ lọna ti ko ṣe e fẹnusọ.

IHA WO NI O YẸ KI A KỌ SI AWỌN PASITỌ WA?
Bi a ti ṣe ri, Ọlọrun lo ma n ṣe awọn eniyan yẹ lati jẹ pasitọ tabi oluṣọ-aguntan tun awọn ọmọ rẹ. Amọ, o tun wa yẹ ki o ye wa pe bi o ti wu ki Ọlọrun ṣe awọn eniyan yẹ to fun iṣẹ iranṣẹ yi, ti a ko ba kọ iha ti o tọ si wọn ati si iṣẹ iranṣẹ wọn, ifẹ, ete ati ipinnu Ọlọrun ko le fi taratara wa si imuṣẹ ninu aye wa, ti o ba tilẹ wa si imuṣẹ rara. Fun apẹẹrẹ, bi o tilẹ jẹ pe Mose jẹ oluṣọ-aguntan tootọ, ti Ọlọrun si ṣe yẹ lati ṣe amojuto awọn eniyan rẹ ati lati ṣe itọni wọn wọ ilẹ-ileri, meji pere ninu awọn agbagba ti o ko jade lati Ijibiti ni o wọ ile ileri naa. Ki ni o si fa? Iha ti wọn kọ si iṣedari rẹ lo fa. Ti awa naa ko ba si kọ iha ti o tọ si awọn ti Ọlọrun yan fun wa gẹgẹ bi oluṣọ-aguntan lati ṣe idari wa wo ile ogo rẹ lalai ni ailabawọn, o ṣeeṣe ki ifẹ, ete ati ipinnu rẹ ma wa si imuṣẹ lori aye wa, paapaa julọ ninu aye yi. (Wo: 1Korinnti 10:1-11)

Nitori naa, o yẹ ki a mọ iha ti o tọ lati kọ si awọn pasitọ wa. Ki wa ni awọn iha naa ti o yẹ ki a kọ si wọn? Akọkọ, a gbọdọ bọwọ fun wọn gidigidi gẹgẹ bi iriju Ọlọrun laarin wa. A ko gbọdọ ri wọn fin tabi ba wọn lopọ pẹlu ailoye. Eyi ko si ki i ṣe nitori pe wọn ṣe iyẹbibiye niwaju Ọlọrun ju wa lọ ṣugbọn nitori iṣẹ ti o gbe fun wọn fun idagbasoke, ipamọ ati iduro-ṣinṣin wa. (Wo: 1Tẹsalonika 5:12-13)

Ekeji, a gbọdọ gbọran si wọn lẹnu, niwọn igba ti ọrọ, irin ati iṣeṣi wọn ba ti wa ni ibamu pẹlu ọrọ ati ifẹ Ọlọrun. A gbọdọ mọ daju wipe Ọlọrun ti fun wọn ni aṣẹ lati ṣe amojuto wa fun idagbasoke, igbeniro ati iduro ṣinṣin ninu imọ Kirisiti ati ninu igbagbọ. Yatọ si eyi, Ọlọrun yoo bere lọwọ wọn bi wọn ba ṣe ṣe itọju ati amojuto wa si. Ko wa ni dara ki wọn ma ṣe iṣẹ wọn laarin wa pẹlu ikẹdun, omije, ibanujẹ tabi ẹru. Eyi ko ni yọri si ire tabi ayọ fun wa. Idi kan pataki si ni yi ti ọpọ ọmọ Ọlọrun ko ṣe ma ṣe orire, ki wọn si gberu si ninu igbagbọ wọn labẹ akoso awọn oluṣọ-aguntan wọn, bi o tilẹ jẹ pe wọn ti pẹ kanrikese ninu ijọ ti wọn wa. Oun naa ni o tun fa ti awọn miran ṣe ti ṣegbe laitọjọ ati lairotẹlẹ, bi o tilẹ jẹ pe awọn pasitọ wọn n gbadura fun wa kikan. Niwọn igba ti a ko ba si yipada, ki a si bẹrẹ si ni mu iṣedari awọn oluṣọ-aguntan wa ni ọkunkundun, nkan ko ni yipada fun wa ninu ọpọ awọn ijọ wa. (Wo: Luuku 13:6-9; 1Kọrinnti 16:10-11; 2Kọrinnti 10:8&13:10; Heberu 13:7&17)

Ẹkẹta, a ko gbọdọ gbagbe rara pe ẹlẹran ara ni awọn pasitọ tabi oluṣọ-aguntan wa naa. Nitori naa, wọn le ṣe aṣiṣe tabi kuna. Idi niyi ti a fi gbọdọ ma fi gbogbo igba tẹle ọrọ Pọọlu ti o sọ wipe, “Ẹ maa ṣe afarawe mi, ani gẹgẹ bi emi ti n ṣe afarawe Kirisiti.” (1Korinnti 11:1) Eyi wa ja si pe niwọn bi awọn pasitọ wa ba ṣe tẹle Kirisiti ni ọrọ, iwa ati iṣe ni ki awa naa ṣe tẹle wọn. Ni ọnakọna ti wọn ko ba ti tẹle, awa naa ko gbọdọ tẹle wọn. Aijẹbẹ, a le tipasẹ eyi kuna tabi ṣubu ninu irinajo igbagbọ wa.

Ẹkẹrin, a gbọdọ mọ pe ojuṣe wa ni lati ran iṣẹ iranṣẹ awọn pasitọ wa lọwọ pẹlu ogbọn wa, nkan ini wa, oye wa, imọ-ijinlẹ wa ati bẹẹbẹẹ lọ. Ki ni idi? Aṣẹ Jesu Kirisiti ni pe ki a ṣe bẹ. Yatọ si eyi, ti awa gan ba mọ ohun ti o tọ fun wa, o yẹ ki oye ye wa pe ti eniyan ba n fi gbogbo igba fi ara rẹ jin lati ṣe itọju ati ikẹ wa, o yẹ ki a ma fi ẹmi imore han loore-koore. Eyi tunmọ si pe ko ki i ṣe isoro ati aniyan wa nikan ni o yẹ ki a jẹ ki wọn jẹ alabapin ninu wọn; o tun yẹ ki a jẹ ki wọn jẹ alabapin iṣorire, ayọ ati ọpọ yanturu wa. Aijẹbẹ, a le ba ijiya Ọlọrun pade, gẹgẹ bi awọn ara igbaani ti ṣe ba pade. (Wo: Malaki 3:8-12; 1Kọrinnti 9:14; Galatia 6:6; Filipi 4:10-19)

ỌRỌ IPARI
Ni akotan, pasitọ ni ẹni naa ti Ọlọrun ṣe yẹ lati jẹ oluṣọ-aguntan fun awọn ọmọ rẹ. Ki a ba si le gbadun iṣẹ iranṣẹ rẹ, a gbọdọ mọ daju, ki a bọwọ fun, ki a ran iṣẹ iranṣẹ rẹ lọwọ, ki a si gbọran si lẹnu ni ibamu pẹlu aṣẹ Ọlọrun.

IBEERE

  • Bawo ni iṣẹ pasitọ ṣe ṣe pataki to ninu ijọ Ọlọrun?
  • Awọn kan a ma sọ wipe wolii ga ju pasitọ lọ ninu ijọ. Njẹ otitọ ni eyi tabi irọ ni?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

ALAYTHIA BIBLE CHURCH (IJỌ OTITỌ BIBELI)
ALAKALẸ ẸKỌ BIBELI ATI ALAYE
ỌJỌRU 11, OGUN 2021
Read More »

Ọna lati di ọta Ọlọrun | Paito J.O. Lawal

Ọjọ: Ogun 08, 2021 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 14

Olufẹ: kaabọ sinu ọsẹ keji ninu oṣu Ogun 2021. Ki oore-ọfẹ Jesu Kirisiti Oluwa wa, ifẹ ti Ọlọrun ati ibadapọ Ẹmi Mimọ wa pẹlu rẹ nisinsinyi ati titi lailai. Amin.

Bi  a ṣe n bẹrẹ ọsẹ tuntun yi, mo fẹ gba ọ niyanju pẹlu ọrọ Apọsiteli Pọọlu, ti o sọ wipe, “Njẹ oju rere eniyan ni emi n wa ni tabi ti Ọlọrun? Tabi emi n fẹ lati wu eniyan, nitori pe, bi emi ba si n wu eniyan, emi ki yoo le ṣe iranṣẹ Kirisiti.” (Galatia 1:10) Njẹ eyi wa tunmọ si pe ko dara rara lati gba oriyin awọn eniyan tabi lati dun wọn ninu? Rara o! Dipo bẹẹ, o tilẹ ṣe pataki ki a kọ lati ma ṣe awọn nkan ti o dun mọ awọn eniyan ninu, paapaa julọ awọn ti a jọ n ṣepọ ninu aye wa. Idi si ni pe eyi yoo mu ki ifẹ, alaafia ati iṣọkan ti o wa ni aarin wọn siwa gbooro si.

Ki si ni Ọlọrun n fẹ laarin awọn eniyan? O n fẹ ifẹ, alaafia ati iṣọkan laarin wọn. Nitorina, nigba ti a ba n lepa lati tẹ awọn eniyan lọrun, ki a ba le mu awọn nkan wọnyi waye, inu Ọlọrun n dun si wa. Ẹnikẹni ti ko ba si ni kẹkọ, ki o si tun ma ṣiṣẹ lati dun awọn eniyan ninu ni ọna yi ko daju pe yoo le fi ara rẹ jin fun ikoraẹni-nijanu ti eniyan gbọdọ ni lati le dun Ọlọrun ninu.

Amọ ṣa o, a nilo lati ṣọra lati ma ṣe ṣẹ Ọlọrun nigba ti a ba n gbiyanju lati tẹ awọn eniyan lọrun. Eyi si ni koko ọrọ ti Pọọlu tẹ pẹpẹ rẹ silẹ fun wa ninu ẹsẹ bibeli yẹn. O fẹ ki a mọ pe bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun ma n fẹ ti a tiraka lati tẹ awọn eniyan lọrun, ki ibaṣepọ wa pẹlu wọn ba le dan mọran, ki o si jẹ eyi ti o ni alaafia, ko fẹ ki a fi eleyi ba ibaṣepọ wa pẹlu rẹ jẹ.

Ki wa ni eyi tunmọ si? Ni kukuru, o tunmọ si pe Ọlọrun funrarẹ ni O gbọdọ sọ fun wa ọna ti a gbọdọ gba tẹ awọn eniyan lọrun. Lotitọ, awọn eniyan le fẹ ki a rin ni awọn ọna kan ki inu wọn ba le dun tabi yọ si wa. Ṣugbọn wọn ko ki i ṣe ẹlẹda wa, bẹẹ si tun ni wọn ko ki i ṣe ẹni ti yoo ṣe idajọ wa tabi pin wa ni ere fun awọn nkan ti a ba ṣe ni aye yi, boya rere ni tabi buburu. Nitori naa, bi o tilẹ jẹ wipe ko buru ki wọn fẹ ki a tẹ wọn lọrun ni ọna kan tabi omiran, igba ti nkan ti wọn n fẹ ba tẹ Ọlọrun nikan ni a gbọdọ ṣe. Ti nkan ti wọn n fẹ ko ba tẹ ẹ lọrun tabi wa ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ, a gbọdọ kọ lati ṣee fun wa tabi lati fi le wọn lọwọ.

Njẹ eyi yo wa mu inu wọn dun bi? Ṣe ki a ṣe nkan ti ko dun mọ awọn eniyan ninu le mu ki inu wọn dun si wa bi? Rara o! Ṣugbọn gẹgẹ bi ọmọ ti o mọ ojuṣe rẹ si Ọlọrun, pataki julọ ninu gbogbo ilepa wa ni aye yi ni ki a tẹ ẹ lọrun, ki a si tun mu inu rẹ dun, ko ki i ṣe ki a tẹ awọn eniyan lọrun ati ki a mu inu wọn dun (2Korinnti 5:9). Lotitọ, ni ọpọ igba, ti a be tẹ Ọlọrun lọrun, ti si mu inu rẹ dun, a o tẹ awọn eniyan lọrun ati mu inu wọn dun pẹlu. Ṣugbọn a ma n ri awọn igba miran ti o jẹ wipe jijẹ itẹwọgba niwaju rẹ yoo gbe wa kọlu awọn eniyan. Eyi yoo si jẹ nitori ikorira wọn fun ododo ati otitọ rẹ (Johanu 3:19-21).

Sibẹsibẹ, bi a ba tilẹ gbe wa kọlu eniyan nitoripe a fẹ tẹ Ọlọrun lọrun, a ko gbọdọ ba ọkan jẹ tabi ba ara jẹ. Idi si ni pe o ṣan pupọpupọ lati jẹ ọta eniyan, ki a si fi igba diẹ jiya ikọsilẹ, eebu ati inunibini wọn ju ki a jẹ ọta Ọlọrun, ki a wa sọnu titi ayeraye. Ti o ba ni awọn eniyan gẹgẹ bi ọta rẹ, Ọlọrun le gba ọ ni ọwọ wọn. Ṣugbọn ti o ba ni Ọlọrun gẹgẹ bi ọta ayeraye rẹ, tani yoo gba ọ lọwọ rẹ? Ko si!

Jemisi sọ wipe, “Ẹyin pansaga ọkunrin, ati pansaga obinrin, ẹ ko mọ pe ibarẹ aye iṣọta Ọlọrun ni? Nitori naa ẹnikẹni ti o ba fẹ lati jẹ ọrẹ aye di ọta Ọlọrun.” (Jemisi 4:4) Njẹ o ri bayi? Ti o ba titori nkankan, boya ẹru, owo, igbadun, ipo tabi ifẹ si oriyin awọn eniyan, di ọrẹ aye, o ti di ọta Ọlọrun niyẹn o. Nkan ti yoo si ti ẹyin rẹ yọ ko ni dara fun ọ tabi fun ọ ni igbadun kankan, boya ni aye yi tabi ni eyi ti o n bọ.

Ranti Pilatu. Kini idi ti o fi tu ọdanran silẹ lati lọ tẹsiwaju ninu igbe aye ẹṣẹ rẹ ṣugbọn ti o da alailẹbi eniyan lẹbi iku? Idi ni pe o fẹ tẹ awọn eniyan lọrun (Maaku 15:15). Nitori naa, o di ọta Ọlọrun ati ọta otitọ ati idajọ ododo nitoripe o fẹ ṣe nkan ti o wu awọn eniyan. Mo wa n wo iru ẹjọ ti o fẹ ro fun un ni ọjọ idajọ, ti o ba jẹ pe ko ri igbala nipasẹ igbagbọ ninu Kirisiti Jesu ki o to ku. Mo si tun n wo nkan ti iwọ naa yoo ri wi fun ni ọjọ ti O ba bẹ ọ wo, ti o ba fi aye gba ara rẹ lati di ọta rẹ nitoripe o fẹ jẹ ọrẹ awọn alagbere, oniṣina, ole, gbajuẹ, oṣo tabi ika eniyan kan tabi omiran. Amọ ṣa o, adura mi ni pe ohunkohun ko ni ṣe aṣeyọri lati sọ ọ di ọta Ọlọrun, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ọna lati di ọta Ọlọrun | Paito J.O. Lawal Read More »

Má sọ ààyè rẹ nù

Sa fun iṣekuṣe | Paito J.O. Lawal

Ọjọ: Ogun 01, 2021 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 13

Olufẹ: Ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu oṣu kẹjọ ọdun yi, oṣu Ogun. Mo gbadura pe ki a ba ọ to aye rẹ lọna ti o o fi le ni iriri ẹkunrẹrẹ ibukun Ọlọrun ninu oṣu naa, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ṣe n bẹrẹ oṣu yi, jẹ ki n ran ọ leti ọrọ Apositeli Pọọlu ti o sọ pe, “Ẹ maa sa fun agbere. Gbogbo ẹṣẹ ti eniyan n da o jẹ ti ode ara; ṣugbọn ẹnikẹni ti o n ṣe agbere, o n ṣe si ara oun tikararẹ. Tabi, ẹyin ko mọ pe ara yin ni tẹmpili Ẹmi mimọ, ti n bẹ ninu yin, ti ẹyin ti gba lọwọ Ọlọrun? Ẹyin kii ṣi i ṣe ti ara yin mọ. Nitori Ọlọrun ti ra yin ni iye kan: nitori naa, ẹ lo ara yin lati yin Ọlọrun logo, ati ẹmi yin pẹlu, ti i ṣe ti Ọlọrun.” (1Korinnti 6:17-20) Ki ni aṣẹ ti a ri gba nibiyi? Oun naa ni pe ki a sa fun agbere. Ki wa ni itumọ ki a sa fun nkan? O tunmọ si pe ki a fi ẹsẹ fẹ ti a ba ti kẹfin nkan naa.

Nitori naa, nigba ti Pọọlu sọ fun wa pe ki a sa fun agbere, nkan ti o n sọ ni pe ki a fi ẹsẹ fẹ ti a ba ti kẹfin ohunkohun ti o ni i ṣe pẹlu agbere. Fun apẹẹrẹ, nigbati aya Potifa bẹrẹ si ni yọ Josẹfu lẹnu pẹlu ifẹkufẹ, oun naa bẹrẹ si ni yẹra fun. Bibeli sọ wipe,“Bi o ti n sọ fun Josẹfu lojoojumọ, ti oun ko si gbọ tirẹ lati dubulẹ ti i, tabi lati ba a lo pọ.” (Jẹnẹsisi 39:10) Njẹ o ri bayẹn? Bi o tilẹ jẹ pe obinrin yi fi ojoojumọ fi ṣe iṣẹ ṣe lati tan Josẹfu lati ba a lopọ, oun kọ gbọ tirẹ tabi duro si gberigberi rẹ. Mo mọ daju pe ti o ba jẹ pe ko ki i ṣe ẹru Potifa ni, ti o kan jẹ ọkan lara awọn oṣiṣẹ rẹ, nṣe ni ko ba fi iṣẹ silẹ ba tirẹ lọ. Ṣugbọn nigba ti ko wa ti ṣeeṣe fun lati fi iṣẹ silẹ, ti o si jẹ dandan ki o ri obirin yi lojoojumọ, oun naa wa fi ṣe iṣẹ ṣe lati ma yago fun.

Ni ikẹyin, ọjọ kan de ti gbogbo awọn ọmọ ọdọ ile naa ko si nile. Ojọ yi gan ni arabinrin yi gba aṣọ rẹ mu, ti o sọ fun pe, “Ani wa ba mi lopọ!” Ṣugbọn o fi asọ rẹ silẹ si lọwọ, o si sa jade kuro ninu ile naa. Ki ni idi ti o ṣe salọ? Idi ni pe o le ko sinu panpẹ agbere ti ko ba ṣe bẹẹ. Wo o, iṣekuṣe jẹ ẹṣẹ ti o ma n gba ọkan ati ara eniyan. Nitori naa, o ko le sọ akoko ti o o dẹ ara rẹ silẹ fun un, ti o ba n fi gbogbo igba wa pẹlu ẹnikẹni ti o n fi gbogbo igba dan ọ wo pẹlu rẹ. Idi ni yi ti a fi pa a laṣẹ fun wa lati sa fun un. Aijẹbẹ, a o ti ṣubu sinu rẹ tan ki a to mọ nkan ti o n ṣẹlẹ.

Ṣugbọn ki wa ni idi ti a fi pa a laṣẹ fun wa lati sa fun oniruuru iṣekuṣe? Kini idi ti a fi paṣẹ fun wa lati jinna rere si nkan ti o da bi ẹni pe o dun un gbadun? Idi ni pe o n ba agọ ara wa, ti o jẹ ti Ọlọrun, jẹ, o si tun n sọ di eleeri. Gẹgẹ bi Pọọlu ṣe fi ye wa ninu awọn ẹṣẹ bibeli yẹn, agọ ara wa ko ki i ṣe tiwa bikoṣe ti Ọlọrun ti o san gbese fun irapada wa. Niwọn igba ti o si ti jẹ pe tirẹ ni wọn n ṣe, Oun naa ti wa bẹrẹ sini gbe inu wọn nipasẹ Ẹmi Mimọ rẹ. Nitori naa, awa nikan kọ ni a n gbe inu agọ ara yi; Ẹmi Ọlọrun naa n gbe inu rẹ pẹlu wa. Idi si niyi ti a ko fi gbọdọ sọ di idibajẹ tabi ki a tabuku rẹ ni ọnakọna. Aijẹbẹ, a le tipasẹ eyi di ẹni iparun, nitoripe Pọọlu sọ fun wa siwaju si pe ti ẹnikẹni ba ba tẹmpili Ọlọrun jẹ, Ọlọrun naa yoo pa ẹni naa run (1Korinnti 3:16-17).

Wayi o, o wa yẹ ki o ye wa pe ibalopo takọtabo gan kọ ni a ni ki a sare jinna si bikoṣe agbere. Nitori naa, ibalopọ takọtabo kọ ni iyọnu; aṣilo rẹ gan an ni wahala. Ipongbẹ fun ibalopo, bi ebi ati ongbẹ, jẹ ẹbun ti Ọlọrun tikararẹ fun wa lati ma fi ifẹ wa han. Ṣugbọn ninu igbeyawo nikan ni a ti fun wa ni aye lati fi ifẹ han nipa pipongbẹ fun ibalopọ. Nitori naa, ti o ko ba i ti lọkọ tabi laya, aṣiṣe gba a ni yoo jẹ fun ọ lati fi ara rẹ jin fun irufẹ ibalopọ yowu ti o ba fi ara rẹ jin fun, yala ibalọpọ laarin ọkunrin si obinrin, ibalopọ laarin ọkunrin si ọkunrin, ibalopọ laarin obinrin si obinrin, ibalopọ laarin ọkunrin si ẹranko tabi ibalopọ laarin obinrin si ẹranko. O tilẹ bu ọ ku paapaa lati ma ba ara rẹ ni ibalopọ, eyi ti wọn n pe loni ni masitọbesan.

Wo o, nṣe ni o n ba agọ ara rẹ jẹ, ti o ba n kopa ninu ọkankan ninu awọn nkan wọnyi. Bi mo si ṣe sọ fun ọ siwaju, ara rẹ ko ki i ṣe tirẹ bi ko ṣe ti Ọlọrun. Nitori naa, igbakugba ti o ba fi nkan ibajẹ rẹ, nṣe ni oun ṣilẹkun aye rẹ silẹ fun iparun. Irufẹ iparun ti o wa le jẹ tabi akoko ti yio wa sori rẹ ni n ko le sọ. O le jẹ iparun idile rẹ lọjọ iwaju tabi iparun ete Ọlọrun lati gbe ọ ga tabi iparun agọ ara rẹ nipaṣẹ awọn aisan buburu kan tabi omiran. Ṣugbọn o di dandan ki iparun naa wa, ti o ba kọ lati ronupiwada ni igba ti o ni anfaani lati ṣe bẹẹ.

Nitori naa, sa fun ẹnikẹni tabi ohunkohun ti o ba le fa ọ wọnu ẹṣẹ agbere. Ma si ṣe fi aye gba irọ ti awọn alaiwa-bi-Ọlọrun, paapaa julọ awọn oṣere wa, n tan kalẹ nipa ibalopọ lati dari rẹ sinu iparun afọwọfa. Ifẹ Ọlọrun ni ki o ko ara rẹ nijanu, ki o si jina si agbere (1Tẹsalonika 4:3-6). Nitori naa, ko si nkankan ti o ṣe ọ, ti o ba yẹra fun agbere, ti o si wa ni mimọ. Ki Ọlọrun si tẹsiwaju lati ma fi okun kun ọkan rẹ lati ṣe eyi, bi o ti wu ki awọn ti o wa ni ayika rẹ ya ọniṣekuṣe to, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni oṣu Ogun 2021 alarinrin.

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Sa fun iṣekuṣe | Paito J.O. Lawal Read More »