Ti ọrọ rẹ ba n bukun fun ọ | Paito J.O. Lawal
Ọjọ: Owewe 26, 2021 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 21
Olufẹ: O jẹ nkan ayọ nla fun mi lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o pari oṣu Owewe 2021. Njẹ ki oore-ọfẹ Ọlọrun alailodiwọn ati ifẹ Kirisiti ti ko ki i jani kulẹ raga bo aye ati ile rẹ ni oṣẹ yi ati ni gbogbo eyi ti o ku ninu ọdun yi, ki o si jẹ ki o rin irin iṣẹgun ni gbogbo igba, ni orukọ Jesu. Amin.
Bi a ṣe n bẹrẹ ọsẹ tuntun yi, mo fẹ ran ọ leti pe ti aye rẹ ba n jẹ alabukunfun nitootọ nipasẹ ọrọ Ọlọrun ti o n gbọ ninu ijọ yi, ojuṣe rẹ ni lati dari awọn elomiran lati ni irufẹ iriri ti o n ni. O ko si nilo lati mọ ọpọlọpọ ẹsẹ Iwe mimọ ki o to le ṣe eyi, yala ni o nilo lati jẹ sọrọsọrọ. Nkankan ti o kan nilo naa ni ikaanu fun awọn ti o wa ni ayika rẹ ti aye wọn le di yiyi pada lọna ti o ga, ti awọn naa ba ni anfaani lati ma gbọ iru ẹkọ inu Iwe mimọ ti o n ri gbọ. Lo ba tan.
Nkan ti mo n sọ ni pe ti o ka ba jẹ alanikanjọpọn ṣugbọn onikaanu fun awọn ti o wa ni ayika rẹ ti aye wọn ti polukumusu nitoripe wọn ko ma gbe wọn ni ibamu pẹlu ọrọ Ọlọrun, o di dandan ki o lo ẹnu rẹ, owo rẹ, foonu rẹ tabi ohunkohun ti o ba wa ni ikawọ rẹ lati fi ọrọ Ọlọrun ti o n yi aye rẹ pada lọ awọn naa pẹlu. Bi bibeli ti ṣe fi ye wa, lẹyin igba ti Filipi ti gbọ ọrọ lati ẹnu Jesu tan, ara rẹ ko balẹ mọ titi o fi wa Nataniẹli kan, ẹni ti o ṣeeṣe ki o jẹ ọrẹ rẹ, ti o si sọ fun pe oun ti ri Mesaya. Bi o tilẹ wa jẹ pe o nira fun Nataniẹli lati gba pe nkan rere kankan le ti Nasarẹti, eyi ti i ṣe ilu Jesu, jade wa, Filipi si ri wipe oun rọọ lati wa ri bi nkan ṣe ri funrarẹ. Bi oun naa si ṣe di apọsiteli Jesu Kirisiti Oluwa niyẹn. (Wo: Johanu 1:43-51)
Njẹ Filipi wa jẹ oniwaasu saaju akoko yi bi? Rara o! Boya ni o tilẹ lero ni akoko naa pe oun yoo pada di apọsiteli. Ṣugbọn nitoripe o mọ daju ṣaka lọkan rẹ iru ẹni ti Jesu jẹ ati pe o fẹ ki ọrẹ rẹ naa di ọmọlẹyin rẹ, o ṣawari rẹ, o si mu tọ Oluwa wa. Ti iwọ naa ba mọ daju ṣaka pe Oluwa n bẹ ni aarin wa ati pe ọrọ rẹ ti o n yi aye wa pada naa le yi aye awọn aladugbo rẹ, ọrẹ rẹ, ẹbi rẹ, akẹgbẹ rẹ ni ibi iṣẹ tabi ile-iwe ati bẹẹbẹẹ lọ pada, iwọ naa yoo dari wọn lati ni iru iriri ti o n ni. Wayi o, bi Nataniẹli, wọn le ma kọkọ gbagbọ pe ere kankan wa fun wọn lati ara nkan ti o n ba wọn sọ. Ṣugbọn iwọ naa kan nilo lati ṣe bi Filipi ni, ki o si ni ki awọn dan ọrọ rẹ wo. Bẹẹni, sọ wipe ki wọn tọọ wo, ki wọn si ri pe rere loluwa (Saamu 34:8).
Ojuṣe rẹ miran, ti o ba jẹ pe lotitọ ni ọrọ Ọlọrun ti o n gbọ ni aarin wa n bukun fun ọ, ni ki o ma pin awọn nkan daradara fun awọn ti o n kọ ọ. Pọọlu sọ eyi si awọn ara Galatia: “Ṣugbọn ki ẹni ti a n kọ ninu ọrọ naa maa ṣe alabaapin ohun rere gbogbo ti o ni fun ẹni ti n kọ ọ.” (Galatia 6:6) Njẹ o ri bayi? Pipin oniruuru ohun rere lara nkan ini rẹ fun awọn ti o n kọ ni ọrọ Ọlọrun ti o njẹ ki aye rẹ lọ siwaju tabi dara si jẹ nkan ti Ọlọrun pa laṣẹ fun ọ lati ṣe. Eyi ki i ṣe ọrọ iyanju rara. Aṣẹ ni o jẹ.
Nitorina, bi ọsẹ ṣe n gori ọsẹ, ti o si n di alabukunfun si pẹlu ọrọ Ọlọrun ti o n gbọ ni aarin wa, nṣe ni o yẹ ki o ma ronu nipa awọn nkan rere ti o o pin fun awọn ti Ọlọrun n lo lati ṣiṣẹ ninu aye rẹ. Eyi si gbọdọ jẹ ṣiṣe ni ibamu pẹlu nkan ti o ni dipo nkan ti o ko ni (2Korinnti 8:12). Bi o ba si n ṣe n ṣe bẹẹ gẹgẹ, ni igbọran si aṣe Ọlọrun, o di dandan ki o ri ere gba lọwọ rẹ, ni ọrun nikan kọ ni o ṣugbọn ni aye yi pẹlu, fun ṣiṣe bẹẹ. Ọna ti yoo wa gba pin ọ lere nikan ni mi o le sọ. Ṣugbọn gẹgẹ bi a ti ṣe fihan wa ninu Iwe mimọ, ere rẹ fun igbọran si aṣẹ rẹ ma n fi gbogbo igba ka eniyan laya, o si tun ma n kọja afojusun tabi ero awọn eniyan.
Fun apẹẹrẹ, nitori pe obinrin opo kan gbọran si lẹnu, ti o si fun Elija ni ounjẹ ti ko ba jẹ ounjẹ ikẹyin fun oun ati ọmọ rẹ, Ọlọrun ri wipe ounjẹ ko tan ninu ile rẹ fun gbogbo ọdun mẹta ati aabọ ti iyan fi wa ni orilẹ-ede Isiraẹli ati wipe ọmọ rẹ ko ku iku aitọjọ (1Awọn Ọba 17). Siwaju si, nitoripe Maria, arabinrin Lasaru, fi odidi agbe ororo oloorundidun oniyebiye kun ara rẹ, Oluwa sọ fun pe nibikibi ti a ba ti waasu ihinrere, o didan ki a darukọ rẹ ati ohun ti o ṣe (Maaku 14:3-8; Johanu 12:1-8). Ọrọ naa si n ri bẹ titi di akoko yi. Nitorina, ti iwọ na ba mu aṣẹ rẹ lori ṣiṣe itọju awọn ti o n bọ ọ pẹlu ọrọ rẹ ni ọkunkundun, iwọ naa ko ni ṣe alaigbere rẹ. Adura mi si pe ki a mu ọkan rẹ ro lati rin ninu igbọran lori ọrọ yi ati lori ọrọ miran yowu ti Ọlọrun ti n fẹ ki o gbọran, ni orukọ Jesu. Amin.
Ki o ni ọsẹ adun o.
Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
Ti ọrọ rẹ ba n bukun fun ọ | Paito J.O. Lawal Read More »



