November 2021

Má sọ ààyè rẹ nù

Jẹ olotitọ ninu iṣẹ isin rẹ si i | Paito J.O. Lawal

Ọjọ: Belu 28, 2021 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 30

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ titi lailai lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ si ọjọ Isinmi ti o kẹyin oṣu Belu 2021. Mo gbadura pe ki didara Ọlọrun ṣan ni akunwọsilẹ ninu aye ati ile rẹ ni eyi ti o ku ki osu naa ati odun yi pari, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ṣe n bẹrẹ ọsẹ yi, mo fẹ gba ọ niyanju pe ki o mu iṣẹ isin rẹ si Ọlọrun ni ọkunkundun ati tọkantọkan. Ki ni idi? Akọkọ, idi ni ki Ọlọrun ba a le lo lati mu ete rẹ ṣẹ ninu aye awọn eniyan. Ti a o ba sin Ọlọrun tọkantọkan ati ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ, a le doju nkan ti o fẹ mu jade nipasẹ nkan ti a n ṣe ru. Eyi ko si ni dara fun wa tabi fun awọn ti a n sin nitori rẹ.

Fun apẹẹrẹ, bi o tilẹ jẹ pe awọn Juu aye igba Jesu Oluwa wa ni awọn alufa, olukọ ofin, Farisi ati Sadusi ti wọn n ṣiṣẹ lati sin wọn, sibẹsibẹ, Oluwa sọ pe wọn da bi agbo aguntan ti ko ni oluṣọ. Eyi tunmọ si pe iṣẹ iranṣẹ awọn adari ẹsin wọn yi ko mu ete Ọlọrun wa si imuṣẹ ninu aye wọn. Ki wa ni idi? Ṣe nitoripe nkankan n ṣe awọn eniyan yi ni? Rara o! Dipo bẹẹ, idi ni pe ọpọ ninu awọ adari ẹsiin wọn yi ni o jẹ alagabagebe, awọn ti ọkan wọn ko mura tan lati sin Ọlọrun ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ. (Wo: Matiu 9:35-36; Matiu 23)

Wayi o, ti a ba ni ki a fi iṣẹ iranṣẹ awọn wọnyi we ti awọn diakoni meje akọkọ ninu ijọ, a o ri pe iyatọ nla gba a ni o wa ni aarin wọn. Idi si ni pe bi o tilẹ jẹ pe a ko ya awọn diakoni yi sọtọ lati waasu bikoṣe lati ṣe amojuto ounjẹ pinpin fun awọn ọmọ Ọlọrun, iṣẹ iranṣẹ wọn yọri si titan kalẹ ọrọ Ọlọrun si ati idagbasoke ijọ rẹ. Ki lo si fa a? Nkan ti o fa a naa ni pe awọn diakoni yi ṣe iṣẹ isin wọn pẹlu ọkan ti o ṣe olotitọ si Ọlọrun. Nitorina, ti a ba jẹ olotitọ si Ọlọrun ninu iṣẹ isin wa, O le lo ohunkohun ti a ba n ṣe, bi o ti wu ki o ma ja mọ nkankan to loju awọn eniyan, lati mu ete rẹ ṣẹ ninu aye awọn eniyan. Amọ ti a ko ba jẹ olotitọ si, bi mo ti ṣe sọ siwaju tẹlẹ, afaimọ ni ki a ma di iṣẹ rẹ lọwọ tabi ba a jẹ.

Bẹẹni, ni awọn igbakan, ni tootọ, Ọlọrun ma n mọn-ọn-mọn foju fo aiṣedeede awọn eniyan si ninu iṣẹ isin wọn, ti yoo si tun mu ki ete rẹ wa si imusẹ nipasẹ nkan ti wọn n ṣe. Fun apẹẹrẹ, igba kan wa ti Mose ati Arọni ṣe aigbọran si, ti wọn si tun ṣe aṣeyọri ninu iṣẹ ti O ran wọn. Eyi tunmọ si pe, pẹlupẹlu aigbọran awọn ọkunrin yi, Ọlọrun si tun ṣe iṣẹ iyanu fun awọn eniyan rẹ nipasẹ nkan ti wọn ṣe. Amọ ṣe wọn wa ri ere gba fun aiṣododo wọn? Oti o! Dipo eyi, nṣe ni a da seria fun wọn gidigidi. (Wo: Numeri 20:1-13)

Lafikun, ti a ba wo igbe aye Samusoni, a ri pe ẹkọ kan pataki ti o kọ wa ni pe o ṣeeṣe ki a jẹ alaiṣootọ si Ọlọrun ninu aye wa tabi ninu iṣẹ isin wa, ki a si tun ma ri iṣẹ tabi ọwọ agbara rẹ ninu ohun ti a n ṣe. Amọ ṣa o, bi a tun ṣe ri nipasẹ itan aye ọkunrin yi, ti a ba tẹsiwaju pẹlu aiṣodo si Ọlọrun ninu aye wa tabi ninu iṣẹ isin wa, akoko naa di dandan ki o de ti yoo jẹ ki oju wa ri ere aiṣododo wa gbogbo, eyi ti o si le ka wa laya. (Wo: Onidajọ 13-16)

Nitorina, ti o ko ba jẹ olododo ninu iṣẹ isin rẹ si Ọlọrun, mọ pe o di dandan ko lẹyin. Ọkan lara ọmọ ti eyi yoo si bi ni pe o ko ni ri ere tabi oriyin gba lọwọ rẹ fun ohunkohun ti o ba n ṣe. Awọn nkan miran ti o si tun le ti ẹyin rẹ jade wa ni emi tabi ẹnikankan ko le sọ. Ṣugbọn o le buru jọjọ. Idi si ni yi ti o fi nilo lati ṣe agbeyẹwo bi iṣẹ isin rẹ si Ọlọrun ṣe dangajia to. Ranti pe a ko le tan an jẹ tabi mu un ṣere. Eyi tunmọ si pe nkan ti o ba gbin naa ni o o ka. (Wo: Saamu 18:25-26; Galatia 6:7-8)

Ti o ba gbin ẹtan, aiṣododo tabi agabagebe ninu iṣẹ isin rẹ si i, eso ti iwọ naa yoo ka di dandan ki o fi han. TI o ba si gbin isododo, ifarabalẹ ṣiṣẹ ati ifẹ ninu iṣẹ isin rẹ si, eso ti o o ka naa yoo fi han. Nitorina, ye parọ tan ara rẹ jẹ mọ nipa iṣẹ isin rẹ si Ọlọrun, ki o si dojukọ otitọ nipa bi o ṣe dangajia si. Bẹẹni, ṣe agbeyẹwo didangajia iṣẹ isin rẹ si Ọlọrun pẹlu imọlẹ ọrọ rẹ, ki o ba le ṣe ohun ti o tọ nipa rẹ. Aijẹbẹ, ara rẹ nikan naa ni o o da lẹbi nigba ti Oun naa ba bẹrẹ si ni pin ọ lere gẹgẹ bi iṣẹ isin rẹ ṣe gba. Mo si gbadura pe o ko ni padanu ere isẹ isin rẹ si Ọlọrun nikẹyinkẹyin tabi ki o jẹ iya lọpọlọpọ nitori pe o ko sin in bi o ṣe tọ ati bi o ṣẹ yẹ, ni orukọ Jesu. Amin

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Jẹ olotitọ ninu iṣẹ isin rẹ si i | Paito J.O. Lawal Read More »

AKỌRI: ILANA FUN IRANWỌ GBIGBA NINU IJỌ AYỌKA: 1Timoti 5:3-16 | Paito J.O. Lawal

ỌJỌRU 24, BELU 2021

AKỌSORI: “Bi obinrin kan ti o gbagbọ ba ni awọn ibatan ti i ṣe opo, ẹ jẹ ki o maa ran wọn lọwọ, ki o ma si ṣe di ẹru naa le ijọ, ki wọn ki o le maa ran awọn ti i ṣe opo nitootọ lọwọ.” (1Timoti 5:16)

ỌRỌ AKỌSỌ
Bi a ti ṣe ri ni inu bibeli, ko si alaini kankan ninu awọn ọmọ Ọlọrun ti o kọkọ gbagbọ ninu Jesu ni igba aye awọn Apọsiteli akọkọ (Iṣe Apọsiteli 4:32-34). Ki si ni idi? Idi ni pe gbogbo wọn, paapaa julọ awọn ti a le pe ni ọlọrọ laarin wọn, n ran ara wọn lọwọ pẹlu awọn nkan ini wọn. Ọpọ ni o ta nkan ini wọn ni akoko yi, ti wọn si fun awọn apọsiteli ni owo ti wọn n pa nibẹ, ki wọn ba le lo wọn lati ran awọn alaini arin wọn lọwọ. Nigba ti o si ṣe, gbogbo wọn ti wọn gbagbọ kuro ni ipo alaini si ipo ẹni ti o ni anito ati aniṣẹku. Eyi si n jẹ ki o ye wa pe o ṣeeṣe ni ijọ wa kọọkan loni ki gbogbo wa ti a jẹ ọmọ Ọlọrun wa ni ipo ẹni ti o ni anito ati aniṣẹku. Awa naa kan nilo lati tọ ipasẹ awọn aṣaaju wa ni, ki a si fi ara wa jin lati ran ara wa lọwọ de ibi ti a o ti le sọ pe ko si alaini kankan ni aarin wa. Amọ ṣa o, ti a ko ba mọ ọna ti o tọ lati ṣe eleyi, o ṣeeṣe ki ififunni wa tabi iran ara wa lọwọ ma mu ete tabi erongba wa wa si imuṣẹ.

Bi a ti ṣe mọ, ọpọ ni o ti ri oniruuru iranwọ gba ninu ijọ ti ko si ja mọ nkankan fun wọn. Ọpọ ni a ti fun ni owo fun okowo tabi lati lọ si ile-ẹkọ, ti wọn si fi gbogbo nkan ti a fun wọn ṣofo. Awọn miran kan tilẹ pa irọ gba iranwọ ninu ijọ ni, ti wọn si wa jẹ ki awọn ti o ran wọn lọwọ ti ika abamọ bọ ẹnu. Idi si niyi ti o fi jẹ pe ọpọ ijọ Ọlọrun loni ni ko ki fi taratara kọbiara si ṣiṣe etọ iranwọ fun awọn ọmọ ijọ wọn. Mo ti lẹ ti gbọ lẹnu ẹnikan ri pe awọn adari ijọ kan sọ wipe, “Ṣọọṣi ko ki i ṣe baba keresi ti o ma n pin ẹbun ọfẹ.” Eyi si bi ẹni ti o gbọ ọrọ yi ninu gidigidi, to bẹẹ gẹẹ ti o fi sọ wipe, “Ti ṣọọṣi ko ba ki i ṣe baba keresi, ta wa ni o yẹ ki o jẹ baba keresi?”

Ti a ba si wo nitootọ, ko da bi ẹni pe nkan ti o buru ni ti ijọ Ọlọrun naa ba n ṣe bi baba keresi. Ṣugbọn ti a ba fi ẹsẹ ọrọ Ọlọrun tọ ọ, a o ri pe ijọ Ọlọrun ko ki i ṣe baba keresi ni tootọ, ti o kan ma n pin ẹbun lọfẹ lofo, lalai fi ti iru eni yowu ti o tọ ọ wa ṣe. Ka tilẹ sọ otitọ, baba keresi gan ti n fi ọgbọn ṣe bayi o. Awọn ti o ba sanwo lati wo o nikan ni o n pin ẹbun fun. Awọn ti ko ba sawọn iworan ko ni ri soju debi pe wọn yoo tilẹ gba ẹbun lọwọ rẹ. Eyi ko wa tunmọ si pe awọn ti o ba fi owo wọn mọ ijọ nikan ni o yẹ ki ijọ Ọlọrun ma ran lọwọ ni igba iṣoro tabi ipọnju. Ko tunmọ si rara pe awọn ti o ba n da idamẹwa ati ọrẹ deede nikan naa ni o yẹ fun iranwọ ijọ. Dipo eyi, o tunmọ si pe ilana wa ninu bibeli ti ijọ Ọlọrun gbọdọ ma tẹle ti wọn ba fẹ ṣe iranwọ fun ẹnikẹni, paapaa julọ ninu ijọ.

ILANA FUN IRANWỌ GBIGBA NINU IJỌ
Lakọkọ naa, a gbọdọ mọ pe ojuṣe wa ni gẹgẹ bi ijọ Ọlọrun kọọkan lati ma ran ara wa lọwọ nipa ti ẹmi ati nipa ti ara. Nitori naa, ko bojumu rara, ko si tun fi han pe a gbagbọ ninu Jesu nitootọ ati pe ifẹ rẹ n gbe inu ọkan wa ti a ba n wo awọn ara wa ti o wa ni ipo aini niran, ti a ko si gbe igbesẹ kankan lati ran wọn lọwọ nigba ti a wa ni ipo lati ṣe bẹẹ (Jemisi 2:14-17; 1Johanu 3:16-18). Amọ sa o, bi mo ṣe ti sọ siwaju, a gbọdọ mọ awọn ilana ti a la kalẹ sinu bibeli lori ọna ti a gbọdọ tẹle lati ma ran ara wa lọwọ ninu ijọ. Aijẹbẹ ifẹ Ọlọrun le ma wa si imuṣẹ nipasẹ iranwọ ti a ba n fun ara wa.

Ki wa ni awọn ilana ti a gbọdọ tẹle? Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, iwọnyi ni pataki julọ lara awọn ilana naa:

  • A gbọdọ ri daju pe ọmọ Ọlọrun ni ẹni ti a fẹ ran lọwọ: Ṣe awọn ọmọ Ọlọrun nikan ni o yẹ ki awọn Kirisitẹni ma ran lọwọ? Rara o! Bibeli sọ wipe, “Njẹ bi a ti n ri akoko, ẹ jẹ ki a maa ṣoore fun gbogbo eniyan, ati paapaa fun awọn ti i ṣe ara wa ninu igbagbọ.” (Galatia 6:10) Yatọ si eyi, o tun sọ wipe, “ Ṣugbọn bi ẹnikẹni ko ba pese fun awọn ibatan rẹ, paapaa fun idile rẹ, o ti ṣẹ ohun naa ti a gbagbọ, o si buru ju alaigbagbọ lọ.” (1Timoti 5:8) Nitori naa, ko ki i ṣe awọn ti o jẹ ọmọ Ọlọrun nikan ni o yẹ ki a ma ran lọwọ gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun. Gbogbo awọn ti Ọlọrun ba fun wa ni aye ati anfaani lati ran lọwọ ni a gbọdọ ma ran lọwọ. Ṣugbọn, a gbọdọ ri daju pe a kọkọ mojuto ile wa tabi idile wa ki a to a ṣe eleyi. Aijẹbẹ, a o jẹbi niwaju Ọlọrun. Yatọ si eyi, a tun gbọdọ mu riran awọn ọmọ Ọlọrun ti o wa ni ayika wa lọwọ, paapaa julọ awọn ọmọ ijọ wa. A si ri pe bibeli fi idi rẹ mulẹ pe a gbọdọ mu riran awọn ọmọ Ọlọrun ti a jọ n ṣepọ ni pataki ju riran awọn ti ko ki i ṣe ọmọ Ọlọrun lọwọ lọ. Idi si ni pe ẹya ara kan naa ni wa ninu Kirisiti Jesu (1Kọrinnti 12). Ko bojumu to lati pa awọn ọmọ ijọ wa ti o ṣe alaini ti, ki a si wa ma lo owo ti awọn ọmọ ijọ miran kojọ lati ma ṣe iranwọ fun awọn alaigbagbọ. Bi awọn aṣaaju wa ninu igbagbọ ti ṣe ṣe kọ ni yẹn. Nitorina, ki a to fun ẹnikẹni ni iranwọ ti o tọ si ọmọ Ọlọrun, paapaa julọ gẹgẹ bi ijọ Ọlọrun, a gbọdọ ri daju ṣaka pe ọmọ Ọlọrun ni ẹni bẹẹ ni tootọ. O si tunmọ si pe o gbọdọ kọja ọrọ ẹnu; a gbọdọ ri ninu iwa ati iṣe ẹni naa pe ọmọ Ọlọrun ti aye rẹ kun fun eso ẹmi ni. Aijẹbẹ, o ṣeeṣe ki ẹni naa ṣi oore-ọfẹ naa lo, ki o si tun mu ipalara ba ijọ Ọlọrun. Apẹẹrẹ eyi si kunlẹ jantirẹrẹ.
  • Iṣedari ijọ ni lati mọ nipa iranwọ ṣiṣe laarin ọmọ ijọ kan si omiran: Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ni igba ti ijọ Jesu bẹrẹ si ni pade, ti wọn si n ran ara wọn lọwọ, awọn apọsiteli ati awọn diakoni ni o n ṣe iṣakoso iṣẹ iranwọ yi. Awọn ni awọn ti o n ta nkan ini wọn n ko owo fun lati pin fun awọn ọmọ ijọ gẹgẹ bi aini ẹnikọọkan wọn ṣe ri. Idi si ni pe awọn ni o wa ni ipo lati tọpinpin, nipa ọgbọn Ẹmi mimọ ati oye ọrọ Ọlọrun, igbe aye ọmọ ijọ kọọkan ati lati mọ irufẹ iranwọ ti wọn nilo. Eyi tunmọ si pe ko ki i ṣe pe awọn eniyan kan dede n mu ẹni ti o ba wu wọn lati ran lọwọ. Ka sọ wipe bẹẹ lo ṣe ri ni, ọpọ ni ko ba kabamọ lori riran awọn ọmọ ijọ kan lọwọ. Bẹẹ si ni ọpọ ko ba tun ṣe kabamọ pe wọn gba iranwọ awọn kan. Yatọ si eyi, ikunsinnu ko ba wa laarin awọn ti wọn ro pe a ko ran awọn lọwọ to. A si ri lotitọ pe akoko kan wa ti awọn opo kan bẹrẹ si ni kun pe wọn awọn ti o n pin ounjẹ ojoojumọ fun wọn ti ti ẹlẹyamẹya ati ojuṣaaju bọ ọrọ naa. Eyi ni o si fa a ti awọn apọsiteli ṣe ni ki wọn yan awọn ti wọn kun fun Ẹmi mimọ, ti wọn si tun ni ọgbọn Ọlọrun ninu wọn lati ma mojutọ ọrọ naa. Nitori naa, ti a ko ba fẹ ṣe aṣiṣe ni riran awọn eniyan lọwọ ninu ijọ tabi ki a mu ki o fa ikunsinu tabi ipalara, a gbọdọ ṣe nipasẹ awọn adari wa ni. Awọn adari wa naa si gbọdọ ṣe ni ọna ti ojuṣaaju ko fi ni wọ ọ nipa fifi aye gba awọn ti o kun fun Ẹmi mimọ ati ọgbọn Ọlọrun lati ṣe amojuto ọrọ naa. (Wo: Iṣe Apọsiteli 4:34-37 & 6:1-7; 1Timoti 5:21)
  • Ẹni naa gbọdọ fi ara rẹ jin fun igbe aye iwa mimọ ati isin ninu ijọ: Yatọ si pe ki eniyan jẹ ọmọ Ọlọrun, bi mo ṣe sọ siwaju, o tun gbọdọ fi ara rẹ han ninu ijọ gẹgẹ bi ẹni ti o fi aye rẹ jin fun iwa mimọ ati sisin Ọlọrun. Fun apẹẹrẹ, Pọọlu, nigba ti o n fun Timoti ni alakalẹ lori awọn nkan ti o yẹ ki o wo ki o to ma ran opo kankan lọwọ pẹlu owo ijọ Ọlọrun, sọ fun pe, “Ma ṣe kọ orukọ opo ti o ba din ni ọgọta ọdun silẹ bi opo ti o yẹ fun iranlọwọ, oun si gbọdọ ti jẹ obinrin oloootọ si ọkọ rẹ, Ẹni ti a lee jẹrii rẹ fun iṣẹ rere, ti o ti tọ ọmọ rẹ bi o ti yẹ, ẹni ti o maa n gba alejo, ti o ti ṣe iranṣẹ fun awọn eniyan mimọ ninu irẹlẹ, ti o si maa n ran awọn ti a n pọn loju lọwọ, ẹni ti n lepa lati ṣe rere” (1Timoti 5:9-10) Pẹlu nkan ti Pọọlu sọ nibiyi, a ri pe ẹni yowu ti ijọ yoo ba ran lọwọ gbọdọ jẹ ẹni ti igbe aye ti o n gbe fi ogo fun Ọlọrun, ti oun naa si tun kun fun iṣẹ rere. Nitori naa, ẹni ti a ko ba le gbẹri rẹ jẹ pe igbe aye rẹ wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun ati pe o tun kun fi iṣe rere ni sisin ijọ Ọlọrun ko lẹtọ si iranwọ ijọ. Aijẹbẹ, ọpọ ni yoo ma lo iranwọ ti wọn gba ninu ijọ lati ṣe iranu tabi lati gbe igbe aye ti ko fi ogo fun Ọlọrun.
  • Awọn ti o n gba iranwọ ko gbọdọ jẹ ọlẹ tabi alaifẹkanṣe: Pọọlu, ninu lẹta rẹ si awọn ara Tẹsalonika kilọ fun wọn lati ma ṣe ran ẹnikẹni laarin wọn lọwọ lati jẹ ọlẹ tabi alainikanṣe. O tilẹ tun sọ siwaju si fun wọn pe ilana ti awọn fun wọn ni pe ẹnikẹni ti ko ba ṣiṣẹ ko lẹtọ si ounjẹ. Eyi tunmọ si pe ọlẹ, boya ninu ijọ ni o tabi ni ibomiran, ko lẹtọ si ounjẹ tabi iranlọwọ. Awọn ti wọn ṣetan lati ṣiṣẹ tọkantara ni iranwọ wulo fun. Idi si ni pe afojusun iranwọ ninu ijọ ki i ṣe lati pọn awọn kan loju ki a ba le tu awọn kan lara bikoṣe lati mu wa de ibi ti ko ti ni si alaini ni aarin wa. Eyi tunmọ si pe ti a ba ran ọ lọwọ loni, ki iwọ naa ba le ran ẹlomiran lọwọ lọla ni. Ti o ba wa ya ọlẹ, njẹ eyi yoo ṣeeṣe bi? Ko ni i ṣeeṣe. Abi ṣe o wa dara ki awọn kan ma fi tọkantara sin Ọlọrun ati fẹ awọn ara wọn pẹlu nkan ini wọn, ki awọn kan si ma fi imẹlẹ ati iwa ọlẹ jẹ igbadun laala wọn? Ko dara rara. Nitori naa, ijọ Ọlọrun ko lẹtọ lati fun ọmọ ijọ alapamaṣiṣẹ kankan ni owo iranwọ. (Wo: 2Kọrinnti 8:13-14; 2Tẹsalonika 3:6-15; 1Timoti 5:9-15)
  • Iranwọ ti o tọ si awọn arugbo ko gbọdọ lọ sọdọ awọn ọdọ: Nkan miran ti a tun fi lọlẹ fun wa ninu bibeli ni pe ko ki i ṣe gbogbo ọmọ ijọ naa ni o nilo iranwọ owo lati ọdọ ijọ. Yatọ si pe eniyan jẹ Kiristiẹni ti a le gba ẹri rẹ jẹ, niwọn igba ti o ba si jẹ ọdọ, ti o ṣi le ṣiṣẹ, ko yẹ ki a tun ma ran lọwọ bi arugbo. Eyi ko sọ wipe ki a ma ran lọwọ rara o, paapaa julọ ti ba wa ninu iṣoro. Amọ a gbọdọ ran lọwọ gẹgẹ bi ọdọ ni, ki i ṣe gẹgẹ bi arugbo ti ko ni ẹnikankan ti o le ran an lọwọ. Eyi si lo fa a ti Pọọlu ṣe sọ fun Timoti pe awọn opo ti ko ba i ti pe ọgọta ọdun ko yẹ ki o wa lori iwe awọn ti ijọ yoo ma fi owo ran lọwọ. Idi si nipe awọn wọnyi si le tun ọkọ ni, ki wọn si tun ma ṣiṣẹ lẹgbẹkan. Aijẹbẹ, a o kan ma ran awọn ọmọ ijọ wa lọwọ lati ya ọlẹ, atojubọle ati alainikannṣe ni. (Wo: 1Timoti 5:9-15)
  • Awọn ti o n gba iranwọ gbọdọ jẹ ẹni ko ni ẹbi ti o le ran wọn lọwọ: Yatọ si awọn ilana ti a ti mẹnuba nipa riran awọn ọmọ Ọlọrun lọwọ ninu ijọ, a tun gbọdo ri daju pe awọn ti a ba fẹ ran lọwọ jẹ awọn ti ko ni ẹbi tabi ara ti o gbagbọ tabi ti o ṣetan lati ran wọn lọwọ. Bi a ṣe fi ye wa ninu bibeli, awọn ti wọn ba ni ọmọ tabi ara ti o le ran wọn lọwọ ko nilo lati tun ma gba iranwọ ijọ Ọlọrun. O yẹ ki a jẹ ki awọn ọmọ wọn tabi ara wọn mọ ojuṣe wọn si wọn ni, ki wọn si maa ṣe e. Eyi tunmọ si pe awa ti a ba ni obi ninu ijọ ko yẹ ki a tun jẹ ki wọn di bukata ijọ. Nṣe ni o yẹ ki a ma mojuto wọn. Aijẹbẹ, asan ni igbagbọ wa ja si, a ko si san ju awọn alaigbagbọ lọ. Nitori naa, a gbọdọ kọ awọn ọmọ Ọlọrun lati ma ṣe jẹ ki awọn ara wọn ti o yẹ ki wọn maa tọju di bukata ijọ Ọlọrun. Idi si nipe eyi yoo fi aye silẹ fun ijọ lati ran awọn miran ti ko ni oluranlọwọ lọwọ. Amọ ti a ko ba jẹ ki eyi ye awọn ọmọ Ọlọrun, a o kan ri pe ijọ Ọlọrun bẹrẹ si ni ru ajaga ti ko yẹ ki o ru ni. Eyi yoo si ran ọpọ lọwọ lati ma gbe igbe aye ojukokoro ati ọkanjua. (Wo: 1Timoti 5:4-8&16)
  • Odiwọn iranwọ si ẹnikẹni gbọdọ wa lori oun ti ijọ ni dipo nkan ti ijọ ko ni: Ko si ẹnikẹni ti o le fun eniyan ni nkan ti ko ba ni. Idi si ni yi ti Ọlọrun fi jẹ ki o ye wa pe gbogbo fififunni wa gbọdọ da lori nkan ti a ni dipo nkan ti a ko ni (2Kọrinnti 8:12). Eyi wa jasi pe ti ijọ Ọlọrun ba fẹ ran ẹnikẹni lọwọ, iranwọ naa gbọdọ wa lori gbedeke nkan ti ijọ ni ni dipo eyi ti ko ni. Idi ni yi ti awọn ọmọ Ọlọrun ti o ba ni lọwọ daradara ṣe gbọdọ ma fi gbogbo igba fi owo tabi nkan iranwọ silẹ fun awọn ara wọn ninu ijọ. Ko ki i ṣe nkan ti o dara ni ki ijọ Ọlọrun ma jẹ gbese nitori pe wọn fẹ ran ọmọ ijọ kan lọwọ tabi nitori pe wọn ni awọn akanṣe iṣẹ kan. Ti a ba fẹ ki a ma ran awọn ọmọ ijọ wa lọwọ lọna ti o peye, nṣe ni ki awa naa bẹrẹ si ni ṣe awọn nkan ti yo jẹ ki o ṣeeṣe.

ỌRỌ IPARI
Riran awọn ọmọ Ọlọrun lọwọ nipa ti ara lati le da duro, ki wọn ma si ṣe wa ni ipo alaini ṣe pataki pupọ. Amọ ti a ko ba tẹle ilana bibeli lati ma ṣe eyi, ko si ni ki a ma kabamọ lori rẹ tabi ki a da rugudu silẹ ninu ijọ.

IBEERE

  • Bawo ni ẹkọ yi ṣe ṣe pataki to fun awọn ọmọ Ọlọrun?
  • Awọn nkan miran wo ni o le sọ pe a tun fi ẹsẹ wọn mulẹ ninu bibeli gẹgẹ bi ilana ti o yẹ ki a tẹle lati ran awọn ọmọ Ọlọrun lọwọ?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

AKỌRI: ILANA FUN IRANWỌ GBIGBA NINU IJỌ AYỌKA: 1Timoti 5:3-16 | Paito J.O. Lawal Read More »

Ma jẹ kan da ọ lẹbi | Paito J.O. Lawal

Ọjọ: Belu 21, 2021 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 29

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lẹkunrẹrẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Belu 2021. Mo gbadura pe ki ọsẹ naa kun akunwọsilẹ pẹlu didara ati ojurere Ọlọrun fun ọ ati fun ile rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ṣe n bẹrẹ ọsẹ tuntun yi, jẹ ki n ran ọ leti ọrọ Pọọlu, ti o sọ wipe, “Nitori naa, ẹ ma ṣe jẹ ki ẹnikẹni maa ṣe idajọ yin ni ti jijẹ, mimu, ọjọ ase, tabi oṣu tuntun, tabi ọjọ isinmi: Awọn ti i ṣe ojiji ohun ti o n bọ, ṣugbọn Kirisiti ni otitọ.” (Kolose 2:16-17) Ki ni koko ọrọ apọsiteli yi nibi yi? Oun naa ni pe a ko gbọdọ gba ki ẹnikẹni ṣe idajọ wa pẹlu ofin Mose.

Ki wa lo fa ti Pọọlu fi sọ eyi? Idi ni pe loorekoore ni a o ma pade awọn eniyan ti wọn yoo fẹ ṣe idajọ wa tabi da wa lẹbi pẹlu ofin yi. Bẹẹni, loorekoore ni a o ma ri awọn eniyan ti wọn yoo fẹ ma gbe odiwọn didangajia wa niwaju Ọlọrun lori bi a ṣe fi ara jin si ofin yi to, ti wọn o si sọ ominira wa ninu Kirisiti di radarada (Galatia 2:4-5). Mo ranti, fun apẹrẹ, bi ọkan lara awọn ọmọbirin kan ti o darapọ mọ awọn akọrin wa nigba ti a kọkọ bẹrẹ awọn ipade wa ṣe bẹrẹ si ni ṣaroye nitori awọn arabinrin wa kan ti wọn n wọ ṣokoto wa fun isin. Nigba ti mo si bere lati mọ idi ti o ṣe n ṣe eyi, o sọ wipe idi ni pe nkan ti wọn n ṣe ko wa ni ibamu pẹlu nkan ti bibeli sọ. Abala bibeli wo si ni o n tọka si? Daju saka, abala ti a ti ri ofin Mose ni.

O wa ṣe ni laanu pe arabinrin yi gan funrarẹ ma n wọ ṣokoto ti ko ba si ni awọn ipade ṣọọṣi. Nigba ti mo si bere lọwọ rẹ pe, “Ṣugbọn mo ti ri ọ ni igboro lọpọ igba pẹlu ṣokoto. Ki wa lo de ti ko fi buru ki iwọ wọ ṣokoto ti o ko ba si ni ipade ṣọọṣi, ti o wa ro pe o buru ki awọn miran wọ ọ wa si ipade ṣọọṣi?” Eyi ti yoosi fi fun mi ni idahun taara, nṣe ni o kan sọ pe, “Mo ṣa mọ pe ko tọ, gẹgẹ bi ọrọ bibeli, ki obirin ma wọ awọn nkan ti o jẹ ti ọkunrin.” Bi o si ṣe dẹkun lati ma wa si awọn ipade ṣọọṣi wa niyẹn patapata.

Wayi o, nkan ti o ṣe yi ko ni orukọ meji ju agabagebe lọ. Agabagebe ni ki eniyan gba pe nkankan ko dara, gẹgẹ bi ọrọ Ọlọrun ti wi, ki o si tun ma ṣe e, boya ni kọrọ tabi ni gbangba. Agabagebe si tun ni pẹlu ti eniyan ba n da awọn miran lẹbi fun ohun ti oun funrarẹ n ṣe. O tilẹ tun wa burujai ti eniyan ba tun wa n da alare ni ẹbi. Ọpọ awọn ọmọ Ọlọrun loni ni o si n da awọn ọmọ rẹ miran lẹbi. Ki si ni idi? Idi naa ni pe wọn ko kọbiara si otitọ inu iwe mimọ.

Fun apẹẹrẹ, gẹgẹ bi Pọọlu ti fi han wa ninu ẹṣẹ bibeli ti o wa ni oke yẹn, ọkan lara awọn otitọ ti a ko ki i kọbiara si ni pe Kirisitiẹni ko gbọdọ gba ki a da oun lẹbi lori nkan ti ofin Mose sọ. Ki si ni idi? Idi ni pe Ọlọrun ko fi igba kankan fun ni ofin yi. Dipo eyi, awọn ọmọ Isiraẹli ni a fun gẹgẹ bi ofin orilẹ-ede wọn nigba ti a ko wọn jade kuro ni Ijibiti. Ọlọrun si tun wa pa a ti sẹgbẹ kan nigba ti Jesu ti mu ohun ti o wa ninu rẹ ṣe, ti O si ti la ọna tuntun ati ọna iye lati sin in silẹ fun wa. (Wo: Ẹkisodu 24:12; Iṣe Apọsiteli 15:1-29; Heberu 8-10)

Njẹ gbogbo eleyi wa tunmọ si pe Kirisitiẹni ko le kọ nkankan nipa Ọlọrun lati ara ofin Mose bi? Rara! O le kọ ọpọlọpọ nkan lati ara rẹ. O ṣi yẹ ko tiraka de oju gongo lati kọ ohunkohun ti o ba le kọ lati ara rẹ. Amọ ṣa o, bi Pọọlu ṣe tẹsiwaju lati fi han wa, ojiji nkan ti Ọlọrun fẹ ki awọn eniyan rẹ mọ nipa rẹ ati nipa aye lasan ni ofin yi jẹ. Inu Kirisiti Jesu gangan ni otitọ wa. Eyi jasi pe ti o ba fẹ mọ otitọ nipa Ọlọrun ati nipa aye nitootọ, Jesu Kiristi Oluwa wa ni o gbọdọ gbajumọ. Oun ni ọna, otitọ ati iye. Ko si si ẹnikẹni ti o le wa si ọdọ Ọlọrun tabi mọ Ọlọrun tabi aye bikoṣe nipasẹ rẹ. (Wo: Johanu 14:4) Nitori naa, kiki otitọ ti a ba fihan nipa rẹ ninu iwe mimọ ni o yẹ ki a kọbiara si, ki a si tun gbajumọ. Lafikun, kiki otitọ ti a ba fihan ninu iwe mimọ nipa rẹ ni a gbọdọ ma lo gẹgẹ bi ipilẹ fun mimọ itunmọ awọn nkan miran ti a ba sọ ninu rẹ. Idi si ni pe otitọ ti a sọ nipa rẹ nikan ni o le sọ wa di ominira lati gbe igbe aye ti Ọlọrun fẹ ki a gbe.

Pẹlu gbogbo nkan ti a n sọ yi, o wa jasi pe a ko gbọdọ gba ki ẹnikẹni lo ogboju tabi ẹtan lati ti wa lati bẹrẹ si ni gbe igbe aye kankan ti ko wa ni ibamu pẹlu awọn nkan ti a fi han wa nipa Jesu Oluwa wa ninu Iwe mimọ. A ko si tun gbọdọ barajẹ tabi ba ọkan jẹ nitoripe inu awọn kan ko dun si wa nitoripe a kọ lati ma gbe aye wa ni ibamu pẹlu ofin Mose tabi awọn aṣa awọn eniyan kan ti o lodi si otitọ Jesu. Ṣugbọn o wa di dandan ki a banujẹ tabi ki a tilẹ gba fun awọn ti wọn fẹ fi ogboju tan wa kuro ninu otitọ Jesu pẹlu ẹsin tabi ifarajin eke, ti a ko ba mọ otitọ ti a kọ nipa rẹ ninu Iwe mimọ, ki a si tun tẹsiwaju ninu rẹ. Nitorina, mu gẹgẹ bi iṣẹ rẹ lati ma fi gbogbo igba kọ nipa otitọ ti a fi han nipa rẹ ninu Iwe mimọ, ki O si tun ma ṣe amulo rẹ. O ko si ni lugbadi asiṣe tabi aṣeju ẹnikẹni.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ma jẹ kan da ọ lẹbi | Paito J.O. Lawal Read More »

Jẹ alaṣepe |Pst. J.O. Lawal |Ọjọ: Belu 14, 2021 |Nọmba: Vol. 10, No. 28

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lailodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Belu 2021. Adura mi fun ọ si ni pe ki o ma fi gbogbo igba gba okun lati jẹ alaṣepe ohun rere gbogbo ti o ba dawọ le, ni orukọ Jesu. Amin.

Pẹlu awọn nkan ti a ri ninu bibeli nipa iṣesi Ọlọrun, ko ki i ṣe ẹnikan ti O ma n dawọ le nkan ti ko ni lọkan lati pari tabi ti ko ni agbara lati pari (Johanu 4:34; Filipi 1:6; Heberu 12:2). Nitorina, ti O ba bẹrẹ iṣẹ rere kankan ninu aye wa tabi fun aye wa, O didan ko pari rẹ, ti a ko ba da lọwọ duro pẹlu aigbagbọ tabi iṣiwawu. Fun apẹẹrẹ, ọpọ ninu awọn ọmọ Isiraẹli ti O ko jade lati Ijibiti ni ko wọ ilẹ Kenani. Ki lo si fa? Ṣe nitoripe ko le pari nkan ti O bẹrẹ ni? Rara o! Dipo bẹẹ, nitori aigbagbọ, aimoore ati oniruuru ifarahan agidi laarin wọn ni wọn ko ṣe wọ ilẹ naa. Nitorina, niwọn igba ti a ko ba ti ya alaigbagbọ tabi alaigbọran si Ọlọrun lẹnu, a le fi sọkan pe yoo pari ohun rere yowu ti O ba dawọ le ninu aye wa, pẹlupẹlu mimu wa lalaafia wọn inu ijọba ayeraye rẹ. (Wo: 1Kọrinnti 10:1-12; Heberu 3:19)

Wayi o, niwọn igba ti Ọlọrun Baba wa jẹ alaṣepe ohun gbogbo ti O ba dawọ rẹ le, awa na, gẹgẹ bi ọmọ rẹ, gbọdọ tọ ara wa lati ni aṣa ki a ma ṣe aṣepe ohun rere gbogbo ti a ba dawọ le tabi ti a ba fa le wa lọwọ. Ranti pe a sọ fun wa ninu bibeli pe ki a jẹ alawokọṣe Ọlọrun, gẹgẹ bi ọmọ rẹ ọwọn (Efesu 5:1). Nitorina, a gbọdọ gbaradi lati ṣe ohunkohun ti a ba fẹ ṣe, yala fun Ọlọrun ni, fun ara wa ni tabi fun awọn miran ni, pẹlu ọkan ti o ṣetan lati ṣe e ni aṣepe.

Ki si ni idi ti eyi fi ṣe pataki? Akọkọ, o ṣe pataki nitoripe ẹni ti o ba ṣe iṣẹ de opin nikan naa ni o le mu idi iṣe naa wa si imuṣẹ ni ẹkunrẹrẹ. Ẹni ti ko ba pari iṣẹ ti o n ṣe, yoo pa ere idi iṣe naa lara ni ọna kan tabi omiran. Fun apẹẹrẹ, ti Jesu Oluwa ko ba pari iṣẹ ti Ọlọrun ran wa si aye lati wa ṣe ni, njẹ igbala wa yoo ṣe e ṣe bi? Rara! Tabi ti agbaṣẹṣe ti o ẹ ki o ṣe ọna kan ba kọ lati pari iṣẹ naa, ṣe awọn ti ọna naa wa fun yoo jẹ igbadun rẹ rara tabi bi o ṣe yẹ ki wọn jẹ? Rara! Nitori eyi, ti a ko ba pari iṣẹ rere yowu ti a dawọ le, a yoo ba idi ti o ṣe yẹ ki iṣẹ naa jẹ ṣiṣe jẹ tabi ki a pa igbadun idi iṣẹ naa lara.

Ekeji, ẹni ti o ba pari iṣẹ ni o pa nkan elo ati akoko fun iṣẹ naa mọ. Ṣugbọn ẹni ti o bẹrẹ nkan, ti ko si pari rẹ kan fi akoko, okun, nkan elo fun iṣẹ naa ati aye rẹ ṣofo lasan ni. A si ri ọpọ ti o jẹ pe wọn kan ma n fi aye, nkan elo fun iṣe, akoko ati oore-ọfẹ ṣofo lasan ni. Idi si ni pe wọn ko ki i fi igba kankan pari iṣẹ rere yowu ti wọn ba dawọ le. Ti awa naa ba si da bi wọn, a jẹ pe nṣe ni awa naa n fi aye wa ati, o tun ṣe e ṣe, aye awọn miran ṣofo lori asan ni.

Idi kẹta ti o ṣe ṣe pataki ki a kọ aṣa ṣiṣe ni aṣepe ohun rere yowu ti a ba dawọ le tabi ti a ba fa le wa lọwọ lati ọwọ eniyan tabi Ọlọrun ni pe ẹni ti o ba pari iṣẹ ti a fun ni a tun le fọwọ ṣọya fun ni iṣẹ miran si. Ẹni ti o pa iṣẹ ti a fun ti tabi ti o ṣe e laabọ ti fi nkankan han nipa ara rẹ, eyi ti o tunmọ si pe ko ni amuyẹ alaṣepe. Iru ẹni yi, bi Oluwa si ṣe fi ye wa, ko yẹ fun iṣẹ iranṣẹ ninu ijọba Ọlọrun. Lotitọ, lẹkọọkan, awọn eniyan le foju fo aini amuyẹ yi lara rẹ, ki wọn si tun fun ni iṣẹ tuntun miran tabi awọn ojuṣe ti o pọ si. Ṣugbọn Ọlọrun ko ni foju fo alebu yi titi ẹni naa yoo fi tọ ara rẹ lati jẹ alaṣepe ohunkokun ti o ba dawọ le (Luuku 6:62).

Idi miran ti o ṣe tun ṣe ṣe pataki ni pe ẹni ti o ba ṣe ni aṣepe iṣẹ rere ti o dawọ le nikan naa ni yoo gba ere ati oriyin lọdọ Ọlọrun ati pẹlupẹlu lọdọ awọn eniyan. Ẹni ti o ba pa iṣẹ ti a fun ti fun idi kan tabi omiran, bi idi naa ṣe le jọ bi ẹni ti o mọgbọn wa to, ko ni gba ere tabi oriyin ti o tọ si alaṣepe iṣẹ. Lotitọ, lẹkọọkan, iru ẹni bẹ le gba ọrọ iwuri lọdọ awọn eniyan fun bi o ṣe gbiyanju. Ṣugbọn Ọlọrun ko ki i fun awọn eniyan ni oriyin nitoripe wọn gbiyanju lati ṣe iṣẹ ti O gbe le wọn lọwọ. Dipo eyi, nṣe ni O ma n fun wọn ni oriyin nitoripe wọn ṣe iṣẹ rẹ laṣepe. Nitorina, ti a ba fẹ ma fi gbogbo igba gba oriyin Ọlọrun lori awọn nkan ti O ba fa le wa lọwọ, a gbọdọ kọ bi a ṣe n pari iṣẹ ti a ba fun wa, ti a ko si ni pa a ti (Ẹkisodu 40:33-34; 1Awọn Ọba 7:51-8:11).

Bawo wa ni a ṣe le tọ ara wa lati jẹ alaṣepe iṣẹ? Akọkọ, a gbọdọ kọ lati ma ṣe fi ara wa jin fun iṣẹkiṣẹ (boya ti Ọlọrun ni o tabi ti eniyan ni) ti a ko ba lero lati ri pe a pari rẹ. Ekeji, a gbọdọ ma fi gbogbo igba farabalẹ ṣe iṣiro nkan ti ohun yowu ti a ba fẹ ṣe yoo na wa ki a to gba lati dawọ le tabi ki a to dawọ le (Luuku 14:28-32). Eyi tunmọ si pe a gbọdọ mọ bi a ṣe to, ki a si gba bi a ṣe to. A gbọdọ mọ nkan ti ipa wa ati nkan ini wa ka ati eyi ti wọn ko ka. Aijẹbẹ, ọpọ igba ni a o ma ri pe a n dawọ le awọn nkan ti a ko ni ipa tabi ipinnu ọkan lati ṣe ni aṣepe. Ki Ẹmi Ọlọrun wa fun ọkan wa ni okun lati mu awọn nkan wọnyi ni pataki, ki a ba dẹkun ati ma fi aye wa ṣofo lori awọn nkan ti ko ni fun wa ni oriyin lati ọdọ Ọlọrun tabi ṣe anfaani fun ọmọniyan.

Ki o ni ọṣẹ ti o ga.

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Jẹ alaṣepe |Pst. J.O. Lawal |Ọjọ: Belu 14, 2021 |Nọmba: Vol. 10, No. 28 Read More »

Fi ara rẹ si ipo iwulo | Pst. J.O. Lawal

Belu 07, 2021 | Nọmba: Vol. 10, No. 27

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ keji ninu oṣu Belu 2021. Mo si wa gbadura pe ki Ọlọrun ro ọ ni agbara lati pọ si ni iwulo ati ilere-lori ninu ijọba rẹ ninu ọsẹ naa ati ni gbogbo eyi ti o ku ni ọjọ aye rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, mo gba adura yi fun ọ nitori pe iwulo awọn eniyan mu ọmu laya Ọlọrun gidigidi. Idi si ni yi ti O ṣe ti bukun ẹnikọọkan ti o wa laye lara wọn pẹlu amuyẹ kan tabi omiran lati jẹ ki wọn le wulo fun ara wọn ati fun awọn yoku ti o wa ni aye. Idi naa si tun ni yi ti O fi bukun ọmọ rẹ kọọkan pẹlu okereju ẹbun ẹmi kan lati jẹ ki wọn wulo, ki wọn si lere lori ninu ijọba rẹ. Nitorina, ti a ko ba wulo ninu ijọba rẹ, paapaa julọ laarin awọn ti a jọ wa ninu ijọ kaa naa, ko ni jẹ nitori pe a ko le wulo ni; dipo bẹẹ, yoo jẹ nitori pe a kọ lati wulo ni.

Bẹẹni, ko si ni ki idi ma wa ti a ko fi ni wulo fun Ọlọrun ati fun awọn eniyan rẹ. O le jẹ ẹru, ọrọ aye wa, anikanjọpọn tabi imẹlẹ. Ṣugbọn bi Oluwa ti ṣe tọka si fun wa, awọn ti o ba fi ara wọn si ipo iwulo pẹlu ẹbun ti Ọlọrun fun wọn nikan naa ni yoo jẹ ki wọn di pataki si ninu aye yi ati ninu ijọba rẹ. Ko si wa si nkan miran tii awọn ti o kọ lati wulo fun le reti ninu aye wọn ju adinku ninu pataki wọn, ilọsiwaju wọn ati awọn ohun rere miran laye yi. (Wo: Luuku 19:12-27)

Nitorina, ti o ko ba fẹ adinku pataki rẹ ninu ijọba Ọlọrun ati ninu awọn nkan ti aye miran, bẹrẹ si ni fi ara rẹ si ipo iwulo pẹlu awọn ẹbun ẹmi rẹ, ẹbun ti ara ti o ni, amuyẹ rẹ, imọ ijinlẹ rẹ ati nkan ini rẹ. O ṣi le bẹrẹ ni kiakia lati arin wa. Nkan akọkọ ti o si nilo lati ṣe eyi naa ni ki o kọkọ ronu nipa bi o ṣe le lo awọn ibukun Ọlọrun ninu aye rẹ lati ran igbagbọ ẹnikọọkan wa lọwọ, ki o si bẹrẹ si ni lo awọn Ibukun naa lati ṣe bẹẹ pẹlu ẹmi itẹriba.

Fun apẹẹrẹ, wo nkan ti a sọ nipa Apolo, lẹyin igba ti a ti fi ọna Oluwa han ni ọna ti o peye: “Nigba ti o si n fẹ kọja lọ si Akaya, awọn arakunrin gba a ni iyanju, wọn si kọwe si awọn ọmọ ẹyin ki wọn ki o gba a: nigba ti o si de, o ran awọn ti o gbagbọ nipa oore-ọfẹ lọwọ pupọ.” (Iṣe Apọsiteli 18:27) Njẹ o ri bayi? Ni kese ti Apolo de si aarin awọn ara Kọrinnti naa ni o ti bẹrẹ si ni ṣe awọn nkan ti o ran igbagbọ wọn lọwọ ni ọna ti o ga.

Iwọ wa n kọ o? Ki ni iwọ naa n ṣe lọwọlọwọ yi lati ran igbagbọ awọn miran ninu ijọ yi lọwọ? Ki ni o n ṣe lati ri pe wọn fi ara wọn jin fun Ọlọrun ati igbe aye ododo siwaju ati siwaju si? Ti ko ba si nkankan ti o n ṣe lati ran idagbasoke igbagbọ wa lọwọ, a jẹ pe o n kuna niyẹn. Ki a si sọ otitọ, o ko yatọ si ẹnikẹni ti o le ma ṣiṣẹ lati pa igbagbọ wa run. Bẹẹ ṣi ni a ri awọn eniyan kaakiri awọn ijọ Ọlọrun loni ti wọn n pa igbagbọ awọn ara wọn run tabi fi idibajẹ ba a dipo ki wọn ma ran an lọwọ. Iru awọn ẹni bẹẹ ko wa ni lọ lai jẹ iya ẹṣẹ wọn, bi a ti ṣe ri ninu iwe mimọ, gẹgẹ bi iwọ naa ti o ko ṣe nkankan lati ran igbagbọ awọn ara rẹ lọwọ ko ṣe ni lọ lai jẹ iya. (Wo: 1Timoti 1:18-20)

Nitori naa, ji kuro loju orun rẹ, ki o si bẹrẹ si ni fi ara rẹ si ipo iwulo fun Ọlọrun ati fun awọn eniyan rẹ. Ẹnu yoo si wa ya ọ lati ri bi aye rẹ yoo ṣe bẹrẹ si ni pọ si ni pataki laarin awọn ọmọ Ọlọrun ati laarin awọn ti aye yi.

Ki o ni ọṣẹ alarinrin.

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Fi ara rẹ si ipo iwulo | Pst. J.O. Lawal Read More »