Gba Eda Tie
AYỌKA: 2KỌRINNTI 12:11-12
AKỌSORI: “O si fi awọn kan fun ni bii apọsiteli…” (Efesu 4:11)
ỌRỌ AKỌSỌ
Lara awọn ti Ọlọrun n yan fun ijọ rẹ lati ṣiṣẹ fun idagbasoke ati pipọsi ni iwulo awọn ọmọ rẹ ninu Kirisiti Jesu ni awọn ti a n pe ni apọsiteli jẹ. Bawo wa ni a ṣe le da wọn mọ? Awọn apẹẹrẹ apọsiteli wo ni a ri ninu bibeli? Njẹ a tilẹ tun ni apọsiteli ninu ijọ loni bi? Iha wo ni o yẹ ki a kọ si wọn? Bawo ni ti awọn eke apọsiteli ṣe jẹ? Ọna wo ni a le gba da wọn mọ? Awọn nkan wọnyi ati awọn miran ti o fara pẹ wọn ni a fẹ ṣe agbeyẹwo ninu ẹkọ yi. Mo si gbadura pe ki Ẹmi Ọlọrun fi imọ ifẹ rẹ ati oye rẹ ti o peye fun wa nipasẹ ẹkọ naa, ni orukọ Jesu Kirisiti Oluwa wa. Amin.
TANI APỌSITELI?
Ni ibamu pẹlu ede Giriki ti a fi kọ pupujọlọ ninu awọn iwe bibeli ti abala majẹmu tuntun, apọsiteli jẹ aṣoju ti a ran lati ṣoju ẹni ti o ran ni ibi yowu ti o ran an lọ. Eyi jasi pe o jẹ ẹni ti ẹni ti o pe ti o si ran niṣẹ ṣe yẹ, ti o si fun ni ohun gbogbo ti yoo nilo lati ṣoju rẹ ni ọna ti o tọ ati ti o yẹ ni ibi ti o ran an lọ. Fun apẹẹrẹ, Mose ni ẹni akọkọ ti a le pe ni apọsiteli tabi aṣoju fun Ọlọrun ti o kọkọ jẹyọ ninu bibeli. Iwe Heberu, ori ikẹta, lati ẹsẹ ikinni sọ eyi nipa rẹ: “Nitori naa, ẹyin ara mimọ, alabaapin ipe ọrun, ẹ gba ijẹwọ wa nipa Jesu ro, ẹni ti i ṣe Apọsiteli ati Olori Alufaa wa. Ẹni ti o ṣe oloootọ si ẹni ti o yan an, gẹgẹ bi Mose pẹlu ti ṣe oloootọ ninu iṣẹ rẹ gbogbo ninu ile Ọlọrun.” (Heberu 3:1-2)
Pẹlu nkan ti ẹni ti o kọ iwe yi sọ ninu awọn ẹsẹ yi, a ri wipe Jesu Oluwa wa funrarẹ jẹ Apọsiteli Ọlọrun. Eyi tunmọ si pe aṣoju Ọlọrun ni o jẹ ati pe gbogbo nkan ti O ṣe nigba ti O wa ninu aye yi jẹ awọn nkan ti Ọlọrun funrarẹ n ṣe. Ranti wipe O sọ eyi fun awọn adari ẹsin Juu lakoko kan: “Loootọ, loootọ ni mo wi fun yin, ọmọ ko le ṣe ohunkohun fun ara rẹ, bi ko ṣe ohun ti o ba ri pe Baba n ṣe: nitori ohunkohun ti o ba n ṣe, wọnyi ni ọmọ n ṣe bẹẹ gẹẹ. Nitori baba fẹran ọmọ, o si fi ohun ti oun tikararẹ n ṣe han an: oun o si fi iṣẹ ti o tobi ju wọnyi lọ han an, ki ẹnu ki o le ya yin. Nitori pe gẹgẹ bi Baba ti n ji oku dide, ti o si n sọ wọn di aaye; bẹẹ ni ọmọ si n sọ awọn ti o fẹ di aaye. Nitori pe Baba kii ṣe idajọ ẹnikẹni. Ṣugbọn o ti fi idajọ le ọmọ lọwọ. Ki gbogbo eniyan ki o le ma fi ọla fun ọmọ gẹgẹ bi wọn ti n fi ọla fun Baba. Ẹni ti ko ba fi ọla fun ọmọ, ko fi ọla fun Baba ti o ran an.” (Johanu 5:19-23)
Nitorina, Apọsiteli ni Jesu Oluwa wa funnrarẹ jẹ si Ọlọrun Baba rẹ ti O ran. Bẹẹni, aṣoju ti a ṣe yẹ lẹkunrẹrẹ ni O jẹ si i. Ko kan dede wa funrarẹ tabi ki O ma ṣe awọn iṣẹ ti O n ṣe ni ibamu pẹlu ifẹ ti ara rẹ. O wa nitoripe Ọlọrun ran an ni. O ṣi ṣe awọn iṣẹ ti O ṣe nitoripe Ọlọrun wa pẹlu rẹ, ti O si tun ṣe e yẹ lati ṣe wọn. Idi si niyi ti idajọ yoo fi wa lori ẹnikẹni ti ko ba gbaagbọ, ki o si bu iyi ti o tọ si Ọlọrun fun un. (Wo: Johanu 8:29; Johanu 20:21; Iṣe Apọsiteli 10:38; Kolose 1:19)
Amọ bi mo ti ṣe sọ siwaju, Jesu kọ ni ẹni akọkọ ti yo jẹ apọsiteli fun Ọlọrun. A ti kọkọ ni Mose gẹgẹ bi apọsiteli rẹ naa. Idi ni yi ti a fi lo iṣẹ iranṣẹ rẹ gẹgẹ bi afiwe fun iṣẹ iranṣẹ Jesu. Bi a ti ri ninu bibeli, Ọlọrun funrarẹ lo fi ara rẹ han Mose, ti O ṣe yẹ, ti O si tun ran lati mu awọn eniyan rẹ, awọn ọmọ Isiraẹli, jade pẹlu ọwọ agbara kuro ni Ijibiti ati lati mu wọn wọ ilẹ Kenani ti O ti ṣe ileri fun awọn baba nla wọn (Ẹkisodu 3-4). Nitorina, aṣoju Ọlọrun lọ si Ijibiti ni ọkunrin yi jẹ. Gbogbo ọrọ ti o si sọ ati awọn iṣẹ ti o ṣe jẹ awọn nkan ti Ọlọrun funrarẹ fẹ sọ ati ṣe lati tu awọn eniyan rẹ silẹ. Idi niyi ti Ọlọrun ṣe sọ fun pe, “Wo o, emi fi ọ ṣe bi Ọlọrun fun Farao: Aarọni arakunrin rẹ ni yoo si maa ṣe wolii rẹ.” (Ẹkisodu 7:1) A si ri wipe Ọlọrun duro ti ọkunrin yi lati mu gbogbo ọrọ ti o sọ wa si imuṣẹ ati lati jẹ ki o le ṣe oniruuru iṣe ami ati iyanu ti o yọri si itusilẹ awọn eniyan rẹ ati ipese wọn fun ilẹ-ileri ti O n mu wọn lọ.
Nitori eyi, ti a ba n sọrọ nipa apọsiteli Ọlọrun, a n sọrọ nipa ẹni naa ti Ọlọrun fi ara rẹ ati agbara rẹ han, ti O si ṣe yẹ lati le ran jade lọ gẹgẹ bi aṣoju rẹ si ibi yowu tabi awọn yowu ti O ni lọkan. Ọlọrun a si wa pẹlu irufẹ ẹni bẹ lati ri pe o ṣe aṣeyọri ninu iṣẹ yowu ti O ba gbe le e lọwọ, niwọn igba ti igbagbọ rẹ ninu rẹ ati igbọran rẹ ko ba ti yẹ.
APỌSITELI JESU
Nibakan naa, ti a ba pe ẹnikẹni ni apọsiteli Jesu Kirisiti, a jẹ wipe ẹni naa jẹ ẹnikan ti Jesu funrarẹ pe, ti o si tun ṣe yẹ lati jẹ asọju rẹ nibi yowu tabi si awọn yowu ti O ba pinnu lọkan rẹ lati ran an si.
Fun apẹẹrẹ, bibeli sọ eyi nipa awọn apọsiteli mejila akọkọ ti Jesu pe, awọn ti a mọ si apọsiteli ọdọ aguntan: “O si gun ori oke lọ, o si n pe ẹnikẹni ti o fẹ sọdọ rẹ: wọn si tọ ọ wa. O si yan awọn mejila, ki wọn ki o le maa gbe ọdọ rẹ, ati ki o le maa ran wọn lọ lati waasu, ati lati ni agbara lati wo arunkarun san, ati lati le awọn ẹmi Eṣu jade.” (Maaku 3:13-14) Ki ni a ri dimu ninu nkan ti a sọ fun wa ninu ẹsẹ bibeli yi? Akọkọ ni pe bi o tilẹ jẹ pe ọpọ ọmọlẹyin ni Jesu ni nigba ti O wa ninu aye yi, ko ki i ṣe gbogbo wọn naa ni o jẹ apọsiteli fun. Awọn mejila pere ni O yan laran wọn lati jẹ apọsiteli rẹ. Nkan ekeji ti a ri dimu ni pe Jesu ṣe awọn ti O yan gẹgẹ bi apọsiteli rẹ yẹ ki O to bẹrẹ si ni lo wọn gẹgẹ bi aṣoju rẹ. O kọkọ mu wọn sọdọ rẹ, ki wọn ba le ma gbe pẹlu rẹ lati kẹkọ ati lati gba agbara ati aṣẹ ti wọn nilo lati ṣe iṣẹ ti O fẹ ki wọn ṣe.
Iṣẹ wo si ni Jesu fẹ ki awọn ti O yan wọnyi gẹgẹ bi aṣoju tabi apọsiteli rẹ ṣe? Awọn iṣẹ ti Oun funrarẹ n ṣe ni. Awọn iṣẹ wo si ni O n ṣe? Akọkọ, O n wasu ijọba Ọlọrun fun awọn eniyan, ki wọn ba le wọ inu rẹ, ki wọn si ma gbe igbe aye ọtun, igbe aye ti Ọlọrun tẹwọgba. Ekeji, O n wo oniruuru aisan ati arun san. Ẹkẹta, O n le awọn ẹmi eṣu jade kuro ninu aye ati agọ ara awọn eniyan ti wọn n pọn loju. Isọri mẹta yi ni a le pin iṣẹ Jesu si ni aarin awọn Juu si. Eyi wa jasi pe idi pataki ti O fi yan awọn mejila ti O yan gẹgẹ bi apọsiteli ni ki iṣẹ rẹ ba a le gbooro si. Gẹgẹ bi eniyan, ko si bi O ṣe fẹ wa ni ibi meji ọtọọtọ ni igba kannaa lati le ṣe irufẹ iṣẹ kannaa. Ṣugbọn ti O ba ni awọn aṣoju tabi iriju ti O ti ṣe yẹ, awọn wọnyi yoo le lọ ṣoju rẹ ni awọn ibi yowu ti O ba fẹ. Wọn o si tun le ṣe ifẹ inu rẹ ni ibi yowu ti O ba ran wọ lọ.
Ṣe o wa ri bẹ fun awọn apọsiteli mejila yi tabi ko ribẹ? O ribẹ fun wọn nitoripe Jesu ṣe wọn yẹ lati le wasu ihinrere, lati le wo arunkarun san ati lati le le awọn ẹmi Eṣu jade. Wo diẹ lara nkan ti a kọ silẹ nipa iṣẹ iriju wọn nigbati ti a ran wọn jade lọ: “Wọn si jade lọ, wọn si waasu ki awọn eniyan le ronupiwada. Wọn si le ọpọ awọn ẹmi Eṣu jade, wọn si fi ororo kun ọpọ awọn ti ara wọn ṣe alaida, wọn si mu wọn larada. Hẹrọdu ọba si gburoo rẹ; (nitori ti okiki orukọ rẹ kan yika) o si wi pe, Johanu Batisi jinde kuro ninu oku, nitori naa ni iṣẹ agbara ṣe n ṣe lati ọwọ rẹ wa.” (Maaku 6:12-14)
Njẹ o ri bayi pe gbogbo awọn apọsiteli yi ni o ṣe awọn iṣẹ ti Jesu ti O ran wọn n ṣe nigba ti O ran wọn jade lọ? Ṣe o si tun ri pe nigba ti wọn bẹrẹ si ni ṣe awọn iṣẹ yi okiki Jesu tan jake-jado ilẹ naa, to bẹẹ gẹẹ ti ọba Hẹrọdu gan fi kiyesi pe nkankan n ṣẹlẹ ni ilẹ rẹ? Ni kukuru, iṣẹ iranṣẹ apọsiteli ni i ṣe pẹlu mimu iṣẹ Jesu gbooro si. Ti a ba si ṣe iṣẹ yi bi o ti ṣe tọ ati bi o ti ṣe yẹ, o di dandan ki okiki rẹ tan kaakiri. Nitorinaa, ẹnikẹni ti o ba pe ara rẹ ni apọsiteli loni, ti ko si mu ki iṣẹ Jesu gbooro si ati ki okiki rẹ tan kalẹ si ko ki i ṣe apọsiteli otitọ. Eyi ko jasi pe ko ki i ṣe Kirisitiẹni nitootọ o. O le jẹ Kirisitiẹni nitootọ. Amọ a ko ṣe yẹ gẹgẹ bi apọsiteli Jesu. Yoo si dara ki o jawọ ninu pipolongo ara rẹ gẹgẹ bi apọsiteli.
Ṣe awọn wọnyi nikan wa ni apọsiteli Jesu ni bi? Rara O. A tun darukọ awọn miran ninu bibeli gẹgẹ bi apọsiteli rẹ. Fun apẹẹrẹ, a darukọ Mataya, Pọọlu, Banaba, Apolo, Adronikusi ati Juniasi gẹgẹ bi apọsiteli rẹ (Iṣe Apọsiteli 1:20; Roomu 16:7; 1Kọrinnti 3:1-9; 1Kọrinnti 9:1-6).
AMUYẸ APỌSITELI
Bawo ni eniyan ṣe le mọ pe apọsiteli ni oun? Ki si ni awọn amuyẹ ti yoo ri ninu aye rẹ? Pataki julọ ninu awọn nkan ti o ma n jẹ ki eniyan mọ pe oun jẹ apọsiteli Jesu ni iwọnyi:
Ifarahan Ọlọrun
Akọkọ lara awọn nkan ti o le jẹ ki eniyan mọ pe apọsiteli Ọlọrun ni oun ni ifarahan Ọlọrun si. Njẹ eyi wa tunmọ si pe gbogbo awọn ti Ọlọrun ba fi ara rẹ han lọna kan tabi omiran naa ni apọsiteli rẹ? Rara o. Wolii, oluṣọ-aguntan, ajinhinrere tabi ẹnikẹni ti o ba jẹ ọmọ Ọlọrun naa le ri ifarahan Ọlọrun fun oniruuru idi. Ṣugbọn ifarahan ti a n sọrọ nipa nibi ni i ṣe pẹlu iṣẹ ti Ọlọrun fẹ gbe le eniyan lọwọ ati awọn nkan ti yoo soro mọ. Eyi tunmọ si pe ki ẹnikẹni to le pe ara rẹ ni apọsiteli, o gbọdọ jẹ pe Jesu ti fi ara han lati sọ fun pe Oun fẹ lo gẹgẹ bi aṣoju Oun.
Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ki Mose to di apọsiteli Ọlọrun si awọn ọmọ Isiraẹli, Ọlọrun ti kọkọ fi ara rẹ han lati pe ati lati sọ iru iṣẹ ti Oun fẹ gbe le lọwọ fun un. Lẹyin igba ti O tun mu awọn ọmọ Isiraẹli yi jade lati Ijibiti tan, Ọlọrun tun pe si ori oke Sinai, nibi ti O tun ti fi ara rẹ han, ti O si fi ọpọlọpọ nkan han nipa ifẹ rẹ fun awọn eniyan rẹ. O tilẹ sọ kedere lọjọ kan fun awọn ẹgbọn rẹ, iyẹn Aarọni ati Miriamu, pe Mose kọja wolii lasan – apọsiteli Oun ni o jẹ. Wo nkan ti O sọ lọjọ naa: “Ẹ gbọ ọrọ mi nisinsinyi: bi wolii Oluwa ba n bẹ ninu yin, emi Oluwa yoo farahan fun un ni ojuran, emi o si ba a sọrọ ni oju ala. Mose iransẹ mi ko ri bẹẹ, oloootọ ni ninu gbogbo ile mi. Oun ni Emi n ba sọrọ ni ẹnu ko ẹnu ati ni gbangba, kii si i ṣe ni ọrọ ti o ṣe okunkun; apẹẹrẹ Oluwa ni oun o si ri: njẹ nitori kin ni ẹyin ko ṣe bẹru lati sọrọ odi si Mose iranṣẹ mi? (Numeri 12:6-8) Nitorina, ifaharan Ọlọrun ti Mose ni ṣe iyatọ rẹ si awọn wolii Ọlọrun miran. Nipasẹ awọn ifarahan yi si ni o ṣe le ṣe iṣẹ ti Ọlọrun gbe le e lọwọ, eyi ti o kọja ki a kan sọ tẹlẹ lasan.
Lafikun, bi mo ti ṣe fi han tẹlẹ, Jesu Oluwa wa naa sọ eyi nipa ara rẹ ati ibasepọ rẹ pẹlu Ọlọrun: “Nitori baba fẹran ọmọ, o si fi ohun ti oun tikararẹ n ṣe han an: oun o si fi iṣẹ ti o tobi ju wọnyi lọ han an, ki ẹnu ki o le ya yin.” (Johanu 5:20) Eyi n fi han wa pe ifarahan Ọlọrun ti Jesu ni ni O ṣe le ṣe irufẹ iṣẹ ti O ṣe, ti O si fi lọlẹ fun awọn ọmọ ẹyin rẹ lati tan kalẹ de gbogbo agbaye.
Njẹ awọn apọsiteli rẹ naa ni irufẹ ifarahan yi bi? Bẹẹni! Niwọn igba ti wọn ti wa pẹlu Jesu ọmọ Ọlọrun, ti O si ti pe wọn, ti O si tun yan wọn lati fi Ọlọrun, ara rẹ ati ifẹ rẹ han wọn, awọn naa wa ni ipo lati ṣe oju rẹ nibikibi ti O ba ran wọn lọ gẹgẹ bi apọsiteli rẹ. Wo nkan ti O sọ lori eyi nigba ti Filipi, ọkan ninu awọn apọsiteli rẹ sọ wipe ki O fi Ọlọrun Baba rẹ han awọn: “Bi akoko ti mo ba yin gbe ti pẹ to yii, iwọ ko si tii mọ mi sibẹ, Filipi? Ẹni ti o ba ti ri mi, o ti ri Baba; iwọ ha ti ṣe wi pe, Fi Baba han wa? Iwọ ko ha gba pe, Emi wa ninu Baba, ati pe Baba wa ninu mi? ọrọ ti emi n sọ fun yin, emi ko da a sọ; Ṣugbọn Baba ti n gbe inu mi, oun ni n ṣe iṣẹ rẹ.” (Johanu 14:9-10)
Lẹyin eyi, O tun sọ eyi fun wọn: “Emi ko pe yin ni ọmọ-ọdọ mi; nitori ọmọ-ọdọ ko mọ ohun ti Oluwa rẹ n ṣe: Ṣugbọn emi pe yin ni ọrẹ; nitori ohun gbogbo ti mo ti gbọ lati ọdọ Baba mi wa; mo ti fi han fun yin.” (Johanu 15:15) Eyi n jẹ ki o yẹ wa pe gbogbo nkan ti o ni i ṣe pẹlu ifarahan Ọlọrun ti Jesu ni nipa iṣẹ ti O fẹ ki O ṣe ni aye yi ti awọn apọsiteli rẹ yi ni lati mọ lati le ṣe oju rẹ ni ọna ti o peye ni O fi han wọn. Aijẹbẹ ni, wọn ko ba ti le tẹsiwaju pẹlu iṣẹ yi, ki wọn si fi idi ijọ rẹ mulẹ laye yi, bi wọn ti ṣe ṣe. A si ri pe nigba ti wọn fẹ yan ẹni ti yoo rọpo Judasi gẹgẹ bi apọsiteli, ọkan lara nkan ti Peteru la kalẹ gẹgẹ bi amuyẹ ti wọn yoo lo ni pe ẹni naa ti gbọdọ ba wọn rin, ki o si jẹ ẹlẹri ohun gbogbo ti wọn ti ri ati ti wọn ti gbọ lati igba ti Jesu ti bẹrẹ iṣẹ iranṣẹ rẹ titi a fi gba a soke sọdọ Ọlọrun. (Wo: Iṣe Apọsiteli 1:21-26)
Bawo wa ni ti awọn miran ti a tun ka si apọsiteli ninu bibeli? Njẹ awọn naa ni irufẹ ifarahan Ọlọrun yi bi? Bẹẹni! bi o tilẹ jẹ pe a ko ni akọsilẹ ifarahan ti gbogbo wọn ni, a ni diẹ lara ti Pọọlu ninu iwe mimọ. Fun apẹẹrẹ, Luuku kọ eyi silẹ nipa apọsiteli yi ati nkan ti o sọ nipa ara rẹ fun awọn adari ẹsin Juu ni akoko kan:
“Ẹnikan si tọ mi wa, Ananaya, ọkunrin olufọkansi gẹgẹ bi ofin, ti o ni orukọ rere lọdọ gbogbo awọn Juu ti o n gbe ibẹ. O si duro ti mi, o si wi fun mi pe, Sọọlu arakunrin, riran. Ni akoko kan naa, mo si siju soke wo o. O si wi fun mi pe, Ọlọrun baba wa ti yan ọ lati mọ ifẹ rẹ ati lati ri Oloootọ nni ati lati gbọ ọrọ lẹnu rẹ. Ki iwọ ki o le ṣe ẹlẹrii rẹ fun gbogbo eniyan, nipa oun ti iwọ ti ri, ti iwọ si ti gbọ.” (Iṣe Apọsiteli 22:12-15)
Njẹ o ri bayi? Ọlọrun mọ-ọn-mọ ya Pọọlu sọtọ ni lati ri Jesu ati lati gbọ ọrọ lẹnu rẹ. Ki si ni idi? Ki o ba le jẹ asoju rẹ ti o peye fun gbogbo eniyan nibikibi ti O ba ran an lọ. Njẹ o wa ri Jesu tabi ko ri bi? O ri Jesu gẹgẹ bi a ti ṣe sọ fun. O si tun gbọ ọrọ lẹnu rẹ pẹlu. Yatọ si eyi, oniruuru nkan ni Jesu fi han an nipa iṣẹ irapada ti O ṣe, ijọba rẹ, ijọ rẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ, eyi ti o jẹ ki o ṣeeṣe fun lati waasu ihinrere pẹlu oye ti o pe ati lati fi idi ijọ Ọlọrun mulẹ ṣinṣin nibikibi ti o lọ. A si wa ri ninu akọsilẹ Pọọlu pe, bi o tilẹ jẹ pe ko wa pẹlu awọn apọsiteli yoku nigba ti wọn n ṣe wọle-wọde pẹlu Jesu, oye ẹni ti Jesu jẹ ati ohun ti o ni ṣe pẹlu ijọba rẹ ti o ni ko kere rara si ti wọn. (Wo: Iṣe Apọsiteli 22:37-21 & 26:12-18; 1Kọrinnti 9:1, 11:23-26 & 15:1-10; 2Kọrinnti 12:1-5; Galatia 1:11-17&2:1-10)
Koko nkan ti a n sọ naa ni pe ẹnikẹni ti o ba jẹ apọsiteli nitootọ, yoo le sọrọ nipa ifarahan Ọlọrun si ati nipa irufẹ iṣẹ ti o gbe fun. Ẹnikẹni ti ko ba si ni ifarahan yi, ifarahan ti o ni i ṣe pẹlu iṣẹ ijọba Ọlọrun ati ọna ti Ọlọrun fẹ ki o gba ṣoju rẹ ni ṣiṣe iṣẹ yi, ko ki i ṣe apọsiteli Oluwa tootọ.
Pipolongo gbogbo ifẹ Ọlọrun
Yatọ si pe ki a ni ifarahan Ọlọrun, bi mo ti ṣe sọ siwaju, ki a to le sọ pe apọsiteli Jesu ni wa nitootọ, ifarahan wa gbọdọ da lori mimu ki iṣẹ ijọba Ọlọrun gbooro si nipasẹ iwaasu ati fifi idi igbagbọ awọn ọmọ Ọlọrun mulẹ, ki wọn ba le dagba soke ninu ẹmi, ki wọn si tun pọ si ni iwulo. Eyi jasi pe a gbọdọ mọ ifẹ Ọlọrun ni ọna ti o ye kooro, ki a si tun le fi ye awọn ọmọ rẹ nipasẹ ọrọ rẹ ni bi o ti ṣe tọ ati bi o ti ṣe yẹ. Apọsiteli Ọlọrun ko ni anfaani lati ṣe ẹyọ awọn abala ifẹ Ọlọrun ti yoo ma kọ awọn eniyan. Rara o. Ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu ifẹ Ọlọrun ni o gbọdọ fi ye wọn, ti yoo si ma lepa la ti fi ye wọn, ki o ba le fi wọn han si Jesu Oluwa gẹgẹ bi pipe ni igbẹyin ohun gbogbo. (Wo: Iṣe Apọsiteli 0:17-27; Efesu 4:11-16; Kolose 1:24-29)
Nitorina, ti a ba sọ pe apọsiteli ni enikan, o kọja ẹni ti o n riran si awọn eniyan tabi ẹni ti Ọlọrun lo lati da ọpọ ijọ rẹ silẹ; o gbọdọ jẹ ẹni ti o ni oye ifẹ Ọlọrun fun awọn ọmọ rẹ ti o ye kooro, ti o si n fi gbogbo igba lepa lati ri pe wọn mọ ifẹ rẹ ati wipe wọn duro ṣinṣin ninu ifẹ naa.
Agbara lati ṣe iṣẹ iyanu ati aṣẹ lori awọn ẹmi eṣu
Bi tun ṣe ri ninu bibeli, ara awọn nkan ti o tun ma n jẹyọ lara ẹnikẹni ti o ba jẹ apọsiteli Ọlọrun nitootọ ni ifarahan agbara Ọlọrun lati ṣe iṣe iyanu ati iwosan ati aṣẹ lati le awọn ẹmi eṣu jade. Lotitọ, gbogbo ọmọ Ọlọrun ni agbara rẹ n gbe inu wọn, ti o si ni ore-ọfẹ lati ṣe amulo agbara rẹ. Bẹẹ si ni, gbogbo ọmọ Ọlọrun ni o ni aṣẹ lori awọn ẹmi eṣu bi a ti ṣe ri ninu bibeli. Amọ ifarahan agbara rẹ ninu wọn lati ṣe iṣẹ iyanu, wo alaisan san tabi le ẹmi ẹṣu jade ko ki i ṣaba farahan ninu aye wọn bi o ti ṣe ma n farahan ninu aye awọn ti o ba jẹ apọsiteli.
Fun apẹẹrẹ, a ri pe Mose, gẹgẹ bi apọsiteli Ọlọrun, ṣe oniruuru iṣẹ ami ati iṣẹ iyanu lati fi idi ọrọ Ọlọrun ati iṣẹ iranṣẹ rẹ mulẹ laarin awọn ti a ran si. Awọn iṣẹ ti o si ṣe dojuti gbogbo awọn oriṣa Ijibiti ati iṣẹ afọsẹ wọn. A si tun ri pe Jesu Oluwa wa naa ṣe oniruuru iṣẹ ami ati iṣẹ iyanu lati fi idi ọrọ Ọlọrun ati iṣẹ iranṣẹ rẹ mulẹ laarin awọn Juu ti a ran si nigba ti O wa ni aye yi. Bẹẹ si ni O tun ṣe le ẹmi eṣu jade kuro ninu ọpọlọpọ eniyan ati agbegbe, ki ifẹ Ọlọrun ba le wa si imuṣẹ ninu aye wọn ati ni aagọ ara wọn.
Bi a tun ṣe wa sọ tẹlẹ ninu ẹkọ yi, ara idi ti Jesu fi yan awọn mejila laarin awọn ọmọ ẹyin rẹ ni ki o ba le fun wọn ni agbara lati wo arunkarun san ati lati le awọn ẹmi eṣu jade (Maaku 3:13-15). Nitorina, iṣẹ iranṣẹ apọsiteli ko ki lọ lalai fi idi ọrọ Ọlọrun ati ifẹ rẹ mulẹ nibikibi ti a ba ti n ṣe nipasẹ oniruuru iṣẹ ami ati iṣẹ iyanu ati lile awọn ẹmi eṣu jade. Idi si ni yi ti Pọọlu ṣe sọ nipa ara rẹ pe, “Nitootọ, emi ti ṣe iṣẹ ami, ati iṣẹ iyanu, ati iṣẹ agbara ti o yẹ laarin yin gẹgẹ bi Apọsiteli ninu suuru gbogbo.” (2Kọrinnti 12:12) Ti a ba si tun wo awọn akọsilẹ ti a ri nipa iṣe awọn apọsiteli igbaani, a o ri pe gbogbo wọn patapata ni Ọlọrun tipasẹ wọn ṣe oniruuru iṣẹ ami ati iyanu, ti O si tun tipasẹ wọn le awọn ẹmi eṣu jade kuro ninu aye ọpọ eniyan. Awọn igba kan tilẹ tun wa ti O lo wọn fun idajọ awọn ti ko rin deede ninu ijọ ati awọn ti o n gbiyanju lati di itankalẹ ọrọ Ọlọrun lọwọ. (Wo: Iṣẹ Apọsiteli 5:1-16, 14:1-3 & 19:11-12)
Eyi n jẹ ki o ye wa pe ti a ba sọ pe apọsiteli ni eniyan, Ọlọrun ti o n ṣoju yoo fun ni agbara lati ma ṣe awọn iṣẹ ti yoo jẹ ki awọn eniyan kọbiara si iṣẹ iranṣẹ rẹ. Ẹnikẹni ti o ba wa pe ara rẹ ni apọsiteli, ti oniruuru iṣẹ ami ati iyanu ati lile awọn ẹmi aimọ jade ko ma farahan lọpọlọpọ ninu iṣẹ-iranṣẹ rẹ ko ki i ṣe apọsiteli. Eyi ko wa tunmọ si pe gbogbo awọn ti o ba n ṣe iṣẹ ami tabi iṣẹ iyanu naa ni apọsiteli. Filipi ajinhinrere ṣe oniruuru iṣẹ iyanu ati ami. O si tun le awọn emi eṣu jade naa lọpọlọpọ. Bẹẹ si ni ko ki i ṣe apọsiteli. Idi si nipe ko ni awọn amuyẹ miran ti a ti mẹnuba ti awọn apọsiteli ma n ni. (Iṣe Apọsiteli 8:5-7)
IWULO IṢẸ IRANṢẸ APỌSITELI
Bi a ti ṣe sọ siwaju, aṣoju ni awọn apọsiteli jẹ fun Ọlọrun ati Jesu ọmọ rẹ. O si ma n ṣe wọn yẹ lati waasu ọrọ rẹ fun ifidimulẹ ijọba rẹ, lati ṣe iṣẹ ami ati iṣẹ iyanu ati le awọn ẹmi eṣu jade. Ṣugbọn awọn ibo gan ni iṣẹ iranṣẹ wọn ti wulo? Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, iṣẹ iranṣẹ apọsiteli ma n wulo pupọ julọ ni awọn agbegbe tabi orilẹ-ede tabi laarin awọn ẹya eniyan ti imọlẹ otitọ Ọlọrun ati Jesu ọmọ rẹ ko i ti fi de rara tabi fi taratara de ati ni awọn ibi ti akitityan Eṣu ti jẹ ki awọn eniyan gbagbe Ọlọrun ati agbara rẹ lati gba wọn la ati lati fun wọn ni isinmi. (Wo: Roomu 15:17-22)
Fun apẹẹrẹ, a ri wipe awọn ọmọ Iṣiraẹli ti fẹrẹ gbagbe Ọlọrun ati agbara rẹ patapata ki O to ran Mose si wọn. Iya ti jẹ wọn to bẹẹ gẹẹ ti wọn kan fi n fi gbogbo igba kerora lasan ni; wọn ko reti igbala lati ọdọ ẹnikankan. Eyi si wa lara idi ti Ọlọrun fi ṣe Mose yẹ lati le ṣe oniruuru iṣẹ ami ati iṣẹ iyanu ti yoo jẹ ki wọn gbaagbọ ati lati tun le kọ wọn, ki o si tun fi idi wọn mulẹ ninu ifẹ rẹ. (Wo: Ẹkisodu 2-4)
Bi a tun ṣe ri ninu bibeli, ki Pọọlu ati awọn awọn alabaṣiṣẹ rẹ ninu Oluwa to lọ si agbegbe Masidonia lati bẹrẹ si ni waasu ni awọn ilu wọn, o kọkọ ri iran kan ninu eyi ti ara Masidonia kan ti n bẹẹ pe ki o rekọja wa si Masidonia lati wa ran awọn lọwọ. Eyi tunmọ si pe okunkun gbilẹ gan ni agbegbe yi to bẹẹ gẹẹ ti wọn fi nilo iṣẹ iranṣẹ apọsiteli fun itusilẹ wọn ati fun ifilọlẹ wọn ninu ifẹ Ọlọrun ati ti Jesu Kirisiti ni kankan. (Wo: Iṣe Apọsiteli 16:6-10)
Lafikun, a ri wipe pataki iṣẹ iranṣẹ Jesu gẹgẹ bi apọsiteli si awọn Juu nigba ti O wa ninu aye yi ni lati tan imọlẹ si okunkun wọn, ki O si fun wọn ni ireti irapada ayeraye Ọlọrun. Lotitọ, wọn ni awọn adari ẹsin ati olukọ ọrọ Ọlọrun loriṣiriṣi ni akoko yi. Amọ, iṣẹ iranṣẹ awọn wọnyi ko pa iṣẹ Eṣu run lọna ti o peye laarin wọn tabi fi idi ifẹ Ọlọrun mulẹ bi o ti ṣe tọ ati yẹ. Jesu funrarẹ rẹ gan pe akiyesi awọn ọmọ ẹyin rẹ si eleyi ni akoko kan, nigba ti O ri pe awọn eniyan naa dabi aguntan ti ko ni olusọ, ti ọpọ ninu wọn si n wọ ọ tẹle kaakiri gbogbo ibi ti O ba lọ. Nitorina, wọn nilo apọsiteli ti yoo ran wọn leti otitọ Ọlọrun ati agbara rẹ nipa kikọ wọn ati ṣiṣe oniruuru iṣẹ ami ati iṣẹ iyanu laarin wọn. Gbogbo nkan wọnyi ni Jesu si ṣe laarin wọn ki O to di pe O fi ẹmi rẹ silẹ fun irapada gbogbo araye. (Wo: Matiu 4:12-17 & 9:35-38; Luuku 4:16-21; Iṣe Apọsiteli 1:1-2)
Nitorina, iṣẹ iranṣẹ apọsiteli wulo pupọ fun titan imọlẹ Ọlọrun sinu okukun awọn eniyan ati fun didari wọn sinu igbagbọ ninu agbara rẹ dipo agbara eṣu. Ko wa si nkan ti o buru nibẹ ti a ba bẹrẹ si ni gbadura si Ọlọrun lati gbe awọn apọsiteli dide fun gbogbo awọn agbegbe, orile-ede ati aṣa agbaye ti imọlẹ rẹ ati ti agbara rẹ ko i ti tan si tabi ti awọn ọmọ rẹ ti o wa nibẹ ti gbagbe rẹ patapata, ti wọn si ti gba ki okunkun gbilẹ laarin wọn ati lori wọn.
AALA APỌSITELI
Njẹ iṣẹ iranṣẹ apọsiteli ma n ni aala bi? Bẹẹni, iṣẹ iransẹ apọsiteli ma n ni aala. Eyi tunmọ si pe, yatọ si Jesu Oluwa ti Ọlọrun ran gẹgẹ bi apọsiteli si gbogbo eniyan, ko si ẹnikẹni ti o le jẹ asoju Ọlọrun si gbogbo awọn ti o wa ni aye. Idi si ni pe iṣẹ ijọba Ọlọrun kọja nkan ti ẹyọ ẹnikan le ṣe. Jesu gan, nigba ti o wa ni aye yi, ko ṣiṣẹ gẹgẹ bi apọsiteli si gbogbo eniyan. Ọpọ igba ni O fi ye awọn eniyan pe awọn Juu nikan ni a ran si ni akoko yi. Nitorina, nigba ti O n kọkọ ran awọn apọsiteli rẹ jade, a ri wipe awọn Juu nikan naa ni O ran wọn si. Ẹyin igba ti O ku, ti O si tun jinde ni O to ran wọn lọ si gbogbo aye lati waasu ihinrere fun gbogbo ẹda. (Wo: Matiu 10:1-5 & 28:16-20; Maaku 16:15; Iṣe Apọsiteli 22:17-21; 1Kọrinnti 9:1; Galatia 2:8)
Pe Jesu wa sọ fun awọn apọsiteli rẹ pe ki wọn lọ si gbogbo aye, ki wọn si ma a waasu ihinrere fun gbogbo ẹda ko wa tunmọ si pe gbogbo awọn gbọdọ lọ si ibi kanna tabi ẹnikọọkan wọn gbọdọ lọ kaakiri agbaye ki wọn to mu iṣẹ iranṣẹ wọn yẹ. Dipo eyi, nṣe ni O ma yan ibi ti ẹnikọọkan wọn yoo lọ fun wọn, ti yoo si tun fi aala iṣẹ iranṣẹ rẹ han. Fun apẹẹrẹ, Pọọlu pe ara rẹ ninu iwe rẹ si awọn ara Galatia ni apọsiteli si awọn Heleni ati Peteru ni apọsiteli si awọn Juu. Njẹ eyi wa tunmọ si pe iṣẹ iranṣẹ rẹ ko bukunfun awọn Juu kankan ayafi awọn Heleni? Rara o! Tabi ṣe o wa tunmọ si pe iṣẹ iransẹ Peteru ko bukunfun awọn Heleni kankan ayafi awọn Juu? Rara o!
(Galatia 2:1-10)
Nkan ti Pọọlu fẹ ki o ye wa ni pe awọn Heleni ni a diidi ran oun si. Nitorina, iṣẹ iranṣẹ rẹ gbooro laarin wọn ju ti awọn Juu lọ. Jesu tilẹ ti sọ fun tẹlẹ pe awọn Juu ko ni tẹwọgba iṣẹ iranṣẹ rẹ. Idi si niyi ti O fi ran an lọ si aarin awọn Keferi. A si ri pe ni gbogbo ibi ti o ti lọ waasu, awọn Juu ni o yọ ọ lẹnu ju. Awọn gan ni o jẹ ki o di ero inu tubu. Nibakan naa, Jesu lo Peteru naa laarin awọn ti ko ki i ṣe Juu. Oun gan tilẹ ni ẹni akọkọ ti o waasu si awọn Heleni, ti Ọlọrun si tipasẹ rẹ sọ lara wọn di atunbi. Amọ ṣa o, aarin awọn Juu ni iṣẹ iranṣẹ rẹ ti gbooro ju. (Wo: Iṣe Apọsiteli 10 & 22:17-21)
Siwaju si, laarin awọn Heleni paapa, iṣẹ iranṣẹ Pọọlu naa tun ni aala. Fun apẹẹrẹ, o sọ eyi fun awọn ara Kọrinnti: “Bi emi ko tilẹ i ṣe Apọsiteli fun awọn ẹlomiran, ṣugbọn dajudaju Apọsiteli ni emi i ṣe fun yi: itori edidi iṣẹ Apọsiteli mi ni ẹyin i ṣe ninu Oluwa.” (1Kọrinnti 9:2) Eyi tunmọ si pe Pọọlu mọ wipe oun ko ki i ṣe apọsiteli si gbogbo eniyan afi awọn ti Ọlọrun fun oun ni ore-ọfẹ lati ṣe iṣẹ iranṣẹ rẹ laarin wọn. Yatọ si eyi, o tun sọ nibomiran pe, “Awa ki yoo ṣogo rẹkọja ara wa, ṣugbọn ero wa ni lati duro ni ala naa, ti Ọlọrun ti pin fun wa, ani lati de ọdọ yin. Nitori awa ko kọja aaye wa rara, bi ẹni pe awa ko de ọdọ yin. Nitori awa tilẹ de ọdọ yin pẹlu ninu iyinrere Kirisiti. Awa ko ṣogo rekọja ala wa, lori iṣẹ ẹlomiran; ṣugbọn awa ni ireti pe, bi igbagbọ yin ti n dagba si, ki ala wa laarin yin pẹlu maa dagba soke si i.” (1Kọrinnti 10:13-15)
Awọn ẹsẹ bibeli yi n jẹ ki o ye wa pe bi eniyan ba jẹ apọsiteli, yoo ni awọn ti a ran ṣi. O le jẹ orilẹ-ede kan ni a ran si tabi ẹya eniyan kan tabi agbegbe kan, lati pe wọn si ọdọ Ọlọrun nipasẹ Jesu, ki o si tun fi idi wọn mulẹ ninu gbogbo otitọ Jesu ti wọn nilo lati mọ nipa kikọ wọn ni ọrọ Ọlọrun ati oniruuru iṣẹ ami ati iyanu. Aarin awọn ti a wa ran si yi ni iṣẹ iranṣẹ rẹ yoo ti mulẹ ju, bi o tilẹ jẹ pe o si le ṣiṣẹ iranṣẹ ni ibomiran ati laarin awọn ọmọ Ọlọrun miran pẹlu. Bẹẹ si ni pẹlu, aarin awọn ti a ran si yi nikan ni o ti gbọdọ gbiyanju lati ma lo aṣẹ rẹ gẹgẹ bi apọsiteli Kirisiti. O wa ṣeeṣe, bi Pọọlu ti ṣe sọ fun awọn ara Kọrinnti, ki Ọlọrun fẹ oju aala iṣẹ iranṣẹ rẹ si. Amọ o gbọdọ ma fi gbogbo igba fi aala iṣẹ iranṣẹ rẹ sọkan, ki o ma ba lo ṣe nkan ti yoo jẹ ki o tẹ laarin awọn ọmọ Ọlọrun miran.
APỌSITELI EKE
Njẹ awọn apọsiteli eke wa bi? Gẹgẹ bi a ti ṣe ri ninu bibeli, wọn wa. Ibikibi ti a ba ti ri awọn ọmọ Ọlọrun ati iransẹ Ọlọrun otitọ, o ṣeeṣe ki awọn eke naa wa nibẹ pẹlu. Fun apẹẹrẹ, Pọọlu sọ eyi fun awọn ara Kọrinnti ninu iwe rẹ kan si wọn:
“Ṣugbọn ohun ti mo n ṣe ni emi o si maa ṣe, ki emi ki o le fopin si iyagan awọn ti n fọnnu pe iṣẹ kan naa ti awọn n sogo ninu rẹ ni awa naa n ṣe pẹlu, ki a le ri wọn gẹgẹ bi awa. Nitori iru awọn eniyan bẹẹ ni awọn eke Apọsiteli, awọn eni i n ṣiṣẹ ẹtan, ti n pa ara wọn da di Apọsiteli Kirisiti. Kii ṣii ṣe ohun iyanu; nitori Satani tikararẹ n pa ara rẹ da bi angẹli imọlẹ. Nitori naa, kii ṣe ohun iyalẹnu mọ bi awọn iranṣẹ rẹ pẹlu ba pa ara wọn da bi awọn iranṣẹ ododo; awọn ẹni ti igbẹyin wọn yoo ri gẹgẹ bi iṣẹ wọn.” (2Kọrinnti 11:12-15)
Eyi jasi pe ni akoko awọn apọsiteli igbani gan awọn eke apọsiteli naa wa pẹlu. Awọn ti wọn n yi ara wọn pada gẹgẹ bi apọsiteli Ọlọrun naa wa nigba naa pẹlu. Pọọlu pe awọn wọnyi ni iranṣẹ Satani. Ki ni idi? Idi ni pe Ọlọrun kọ ni o ran wọn. Ba wo wa ni a wa ṣe le mọ wọn? Akọkọ, a le mọ wọn nipa titẹle ọrọ Jesu Oluwa wa lori bi a ṣe le mọ iranṣẹ rẹ otitọ yatọ si awọn eke. O sọ fun wa pe nipa eso ti awọn eniyan ba n so ni a o fi mọ boya iranṣẹ Oun niwọn lotitọ tabi bẹẹkọ (Matiu 7:15-20).
Nitorina, ẹnikẹni ti o ba pe ara rẹ ni apọsiteli Jesu, ti awọn eso Ẹmi Kirisiti ko si farahan laye rẹ ko ki i ṣe apọsiteli otitọ tabi ki o jẹ apọsiteli ti o ti ṣubu sinu ẹsẹ, ti o si nilo ironipiwada ati imupadabọsipo. O wa ṣeeṣe ki ẹni bẹẹ ma ṣe oniruuru iṣẹ iyanu ati iṣẹ ami. Eyi ko tunmọ si pe ko ki i ṣe eke. Awọn eniyan le lo ẹmi oṣo tabi ti ajẹ lati ṣe iṣẹ iyanu ati iṣẹ ami gẹgẹ bi ọrọ bibeli (2Tẹsalonika 2:9-10). Idi si ni yi ti a ko fi le sọ daju pe apọsiteli Jesu ni ẹnikan nitori pe o n ṣe iṣẹ ami ati iyanu tabi nitoripe o n da ijọ silẹ kaakiri nikan. Ti igbe aye rẹ ko ba ti dọgba pẹlu ọrọ Ọlọrun, ti ko si duro siwaju awọn ọmọ Ọlọrun gẹgẹ bi apẹẹrẹ nkan ti Ọlọrun fẹ ẹ ri ni aye wọn, ko ki i ṣe apọsiteli otitọ.
Ọna kẹji ti a tun fi le mọ eke apọsiteli ni ki a wo irufẹ iṣẹ ti o n ṣe. Bi a ti ṣe sọ tẹlẹ, a ko le sọ pe apọsiteli ni eniyan nitori awọn iṣẹ ti o n ṣe nikan. Amọ ṣa o, ẹni ti iṣẹ iranṣẹ rẹ naa ko ba wa ni ibamu pẹlu ọrọ bibeli lori iṣẹ iranṣẹ apọsiteli naa ko ki i ṣe apọsiteli otitọ. O le ma fọn ẹnu, ki o si ma sogo lori awọn nkankan ti o n ṣe, bi awọn ti Pọọlu sọrọ wọn ninu iwẹ rẹ si awọn ara Kọrinnti. Ṣibẹsibẹ, ko ki i ṣe apọsiteli otitọ. Iru wọn ni wọn ki mọ ala iṣẹ iranṣẹ wọn, ti wọn o si ma gbiyanju lati paṣẹ fun gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun ti wọn ba ri tabi ti wọn ba fi aye gba wọn. Awọn wọnyi ma n ba iṣẹ Ọlọrun jẹ kẹyin naa ni ti wọn ko ba tete ronupiwada.
IHA WO NI O YẸ KI A KỌ SI WỌN?
A wa gbọdọ yẹra fun ẹnikẹni ti a ba ti fidi rẹ mulẹ, ni ibamu pẹlu ọrọ bibeli, pe ko ki i ṣe apọsiteli Kirisiti. Jesu yin awọn ijọ Efesu fun eyi ninu lẹta rẹ si wọn ti o wa ninu iwe ifihan, eyi ti o sọ wipe: “Emi mọ iṣẹẹ rẹ ati laalaa rẹ, ati ifarada rẹ, ati bi ara rẹ ko ti gba awọn ẹni buburu: ati bi iwọ si ti dan awọn ti n pe ara wọn ni apọsiteli, ti wọn kii ṣi i ṣe bẹẹ, ti iwọ si rii pe elekee ni wọn.” (Ifihan 2:2-3)
Njẹ o ri bayi? Ki a to le mọ iru iha ti o yẹ ki a kọ si ẹnikẹni ti o ba pe ara rẹ ni apọsiteli, a kọkọ gbọdọ dan an wo naa ni ibamu pẹlu ọrọ Ọlọrun. Ti a ba si ri pe olotitọ ni, nṣe ni o yẹ ki a gba a tọwọ-tẹsẹ gẹgẹ bi a ti a ti ṣe gba Jesu fun ara rẹ, ki a ba le jẹ ere iṣẹ iranṣẹ rẹ. Eyi jasi pe niwọn igba ti a ba ti mọ pe apọsiteli otitọ ni ẹnikan ti Ọlọrun fun wa ni anfaani lati pade tabi lati pin ninu iṣẹ iranṣẹ rẹ, a gbọdọ lepa lati ran oun ati iṣẹ iranṣẹ rẹ lọwọ ni ibamu pẹlu ọrọ bibeli. Eyi si lere lori pupọ fun wa. (Wo: Matiu 10; Luke 10:1-12; 1Kọrinnti 9:1-14; Filipi 4:10-19)
Amọ ti a ba ri pe eke ni ẹni naa ti o n pera rẹ ni apọsiteli fun wa, a gbọdọ yẹra fun, ki a si tun kilọ fun awọn ọmọ Ọlọrun ti o wa ni sakani wa lati ṣe bẹẹ gẹgẹ. Aijẹbẹ, o ṣeeṣe ki a kopa ninu ẹṣẹ rẹ tabi ki a ko sinu panpẹ rẹ ti o dẹ lati ba aye wa jẹ. (Wo: Iṣe Apọsiteli 20:29-31; 2Johanu 10-11)
ỌRỌ IPARI
Iṣẹ iranṣẹ apọsiteli ṣe pataki pupọ, paapaa julọ lati tan imọlẹ sinu aye awọn eniyan ni awọn agbegbe, ẹya ati orilẹ-ede ti ko i ti fi aye gba ihinrere Jesu tobẹ jubẹ lọ. Amọ ṣa o, awọn ti Jesu funrarẹ ba ṣe yẹ nikan ni o lẹ ṣe iṣẹ yi bi o ti ṣe tọ ati bi o ti ṣe yẹ. Nitorina, ti a ba mọ ẹyakẹya tabi edekede tabi agbegbekagbegbe ti ihinrere Jesu ko i ti fi taratara mulẹ nibẹ tabi ti awọn ọmọ Ọlọrun ti o wa nibẹ ti ku patapata ninu ẹmi, ẹtọ wa ni lati gbadura si Ọlọrun ki o gbe apọsiteli dide fun irufẹ agbegbe naa, ki a ba le ri ikore awọn ọmọ rẹ lati ibẹ.
IBEERE
- Njẹ a ri awọn ti a le pe ni apọsiteli ninu ijọ Ọlọru loni? Ki ni o jẹ ki o ro pe apọsiteli ni wọn?
- Bawọ ni ẹkọ yi ṣe ran imọ ati oye ti o ni nipa iṣẹ iranṣẹ apọsiteli lọwọ si?
Lati ọwọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)