Ere ẹni ami-ororo Oluwa | Pst. J.O. Lawal |Ẹrẹna 27, 2022 | Nọmba: Vol. 10, No. 47.
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lailodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Pẹlu idunnu ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ati awọn ọjọ ti o kẹyin Oṣu Ẹrẹna 2022. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun jẹ ki ojurere rẹ ru bo ori aye rẹ lọsẹ yi, ki o si dari oniruuru ohun rere ati ohun daradara ti iṣẹ aṣekara ko le fun ọ lailai sọdọ rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.
Wayi o, ko to lati kan ma gbadura si Ọlọrun lati jẹ ki ojurere rẹ bori aye wa, ki oniruuru nkan iyanu si ma ṣẹlẹ si wa. O tun ṣe pataki pẹlu ki awa naa ma ṣe awọn nkan ti yoo jẹ ki ojurere rẹ ṣiṣẹ ninu aye wa. Ọkan lara awọn nkan naa si ni lilawọ si awọn ti Ọlọrun ti fi ami ororo rẹ yan lati ma bọ wa pẹlu ọrọ rẹ, lati ma gbadura fun wa ati lati ma tọ wa ni ipa ọna ododo rẹ. Wo nkan ti Jesu sọ nipa eyi: “Ẹni ti o ba gba yin, o gba mi, ẹni ti o ba si gba mi, o gba ẹni ti o ran mi. Ẹni ti o ba gba wolii ni orukọ wolii, yoo jẹ ere wolii; ẹni ti o ba si gba olododo ni orukọ olododo yoo jẹ ere olododo. Ẹnikẹni ti o ba fi kiki aago omi tutu fun ọkan ninu awọn onirẹlẹ wọnyi mu nitori orukọ ọmọ-ẹyin, loootọ ni mo wi fun yin, ki yoo padanu ere rẹ.” (Matiu 10:40-42)
Njẹ iwọ naa ri bayi? Ẹnikẹni ti o ba gba ẹni ami-ororo Ọlọrun nitori pe o gba pe lotitọ Ọlọrun ni o ran ko ni ṣalai ri ere ẹni ami-ororo naa gba. Bi o tilẹ jẹ pe ife omi tutu kan lasan ni o fun un mu, ko ni ṣalai ri ere rẹ gba. Irufẹ nkan ti ere yi yoo wa jẹ nikan naa ni ẹnikẹni ko le sọ. Iyẹn ni i ṣe pẹlu bi Ọlọrun ba ti ṣe dari ẹni ami-ororo rẹ naa lati bukun fun ẹni yowu ti ọrọ naa kan.
Fun apẹẹrẹ, ere ti arabinrin Ṣunemu gba lati ọdọ Ọlọrun nipasẹ Eliṣa ni ọmọkunrin kan ti Satani ko ri pa jẹ, lẹyin igba ti o ti jẹ agan fun ọdun melokan (2 Awọn Ọba 4:8-37). Lafikun, ere ti opo Sarefati gba lọwọ Ọlọrun lati ipasẹ Elija ni ipamọ aye rẹ ati ti ọmọ rẹ ni gbogbo akoko ti iyan ti o buru jọjọ ni ilẹ naa fi mu un (1Awọn Ọba 17). Bẹẹ si ni ere ti Maria, arabinrin Mata, gba lọwọ Jesu Oluwa fun lilawọ rẹ si ni orukọ ti a o ma fi gbogbo igba mẹnuba ati gboriyin fun ninu ijọba Ọlọrun ati ni ibi gbogbo ti a ba ti polongo ihinree (Matiu 26:6-13)
Nitorina, ko si ẹni naa ti o le sọ ni pato ọna ti Ọlọrun yoo gba pin awọn ti o lawọ si awọn iranṣẹ rẹ lere. Amọ o di dandan ki O pin wọn lere pẹlu awọn nkan ti owo, iṣẹ aṣekara tabi ọpọlọ pipe ko le ri gba lailai. O wa ṣeni laanu pe ọpọ wa ni a n padanu awọn nkan wọnyi. Ko si ki i ṣe nitoripe a ko le ri wọn gba ni a ṣe n padanu wọn. Idi ti a ṣe n padanu wọn ni pe a jẹ ahun, ọkanjua tabi alaikọbiara si nkan. Elo ni ife omi tutu kan fẹ naa ẹnikẹni ninu wa? Owo ti ko ja mọ nkan ni. Sibẹsibẹ, ọpọ wa ni a n padanu awọn ire ti ko ba jẹ ti wa nitoripe a lọra lati fun awọn ẹni ami-ororo Ọlọrun arin wa ni ife omi lasan. Iwo naa gbe ọrọ yi yẹwo.
Njẹ mo wa n sọ pe nṣe ni ki o ma le pasitọ tabi adari ijọ rẹ kaakiri pẹlu ife omi, boya oungbẹ n gbẹ tabi ko gbẹ? Rara o! Abi ṣe mo wa n sọ pe niwọn igba ti o ba ti n fun awọn adari ijọ rẹ ni ife omi tutu mu loorekoore, o ti ṣe nkan ti Ọlọrun fẹ ki o ṣe? Rara o! Lotitọ, ti o ba jẹ pe ife omi nikan ni agbara rẹ gbe nitootọ lati fi ran adari ijọ rẹ ati ẹni ami-ororo ti Oluwa ran si ọ lọwọ, ko si nkan ti o buru nibẹ. Ọlọrun yoo pin ọ lere fun un, ni ibamu pẹlu oṣuwọn rẹ.
Amọ ṣa o, otitọ ibẹ ni pe ọpọ ninu wa ni o ri jajẹ kọja ki o kan ma gbe ife omi kaakiri. Ọlọrun ko reti pe ki a ṣe kere si bi a ti ṣe to niwaju rẹ. Aijẹbẹ, nṣe ni a o ma yan ara wa jẹ. Wo nkan ti O sọ ninu ofin Mose si awọn eniyan rẹ lori ọrọ yi: “Ṣugbọn ifibu ni fun ẹlẹtan naa, ti o ni akọ ninu ọwọ-ẹran rẹ, ti o si jẹjẹẹ, ti o si fi ohun abuku rubọ si Oluwa; nitori Ọba nla ni Emi, ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, ẹru si ni orukọ mi laarin awọn keferi.” (Malaki 1:14) Njẹ o ri bayẹn? Amọ ṣa, a dupẹ lọwọ Ọlọrun pe a ko si labẹ egun kankan nitoripe Jesu ti ba wa yanju ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu egun. Ṣugbọn, a kọ eyi silẹ lati kọ wa pe iwa ailọwọ gbaa ni lati fun Ọlọrun tabi awọn iranṣẹ rẹ ni nkan ti o kere si ibukun rẹ lori aye wa. Irufẹ iwuwasi yi ni o si ṣọ Ananaya ati Safira aya rẹ di ẹni ti Ọlọrun n lu pa dipo ki o pin ni ere (Iṣe Apọsiteli 5:1-11).
Adura mi wa ni pe a ko ni farapa, di oku tabi di ẹni ti a n rẹ silẹ ni ibi ti o yẹ ki Ọlọrun ti san wa lẹsan pẹlu oniruuru nkan daradara. Amọ awa naa gbọdọ tọ ara wa lati ni iwuwasi ti o tọ lori lilawọ si Ọlọrun ati awọn ti O n lo lati bukun fun wa. Ki Ẹmi rẹ rere si jẹ ki eyi ri bẹ fun ẹnikọọkan wa, ni orukọ Jesu. Amin.
Ọsẹ ayo o.
Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
Ere ẹni ami-ororo Oluwa | Pst. J.O. Lawal |Ẹrẹna 27, 2022 | Nọmba: Vol. 10, No. 47. Read More »



