May 2022

Ọ̀NÀ LÁTI TỌ́ ARA RẸ SÍ ÌWÀ-BÍ-ỌLỌ́RUN (2) | Pst. J.O Lawal |TÍMÓTÌ 4:7-11 | ỌJỌ́RÚ 25, ÈBÌBÍ 2022

ÀKỌ́SÓRÍ: “Má ṣe fetí sí ọ̀rọ̀ tàbí ìtàn asán; ṣùgbọ́n tọ́ ara rẹ sí ìwà-bí-Ọlọ́run.” (Tímótì 4:11)

Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ

Ninu ẹkọ ti a kọ kẹyin lori ọna lati tọ ara wa si iwa-bi-Ọlọrun, a mẹnuba awọn ipese Ọlọrun fun wa lati gbe igbe aye iwa-bi-Ọlọrun ati pataki ki a ṣe amulo wọn. Ki si wa ni awọn ipese wọnyi? Awọn naa ni Ẹmi mimọ, ọrọ Ọlọrun, anfaani adura gbigba, anfaani ibaṣepọ pẹlu awọn ọmọ Ọlọrun ati iṣẹ iranṣẹ awọn angẹli. Ninu ẹkọ eyi ẹwẹ, a tun fẹ wo igbesẹ miran ti a nilo lati ma a gbe lati le tọ ara wa si iwa-bi-Ọlọrun. Lalai si mọ igbesẹ yi, ki a si ma gbe e, yoo ṣoro fun wa lati ma fi gbogbo igba gbe igbe aye ẹni ti o wa bi Ọlọrun. 

YẸRA FUN IBASEPỌ AIDỌGBA PẸLU AWỌN ALAIGBAGBỌ

Igbesẹ miran wo lo wa yẹ ki a ma gbe lati tọ ara wa si iwa-bi-Ọlọrun yatọ si pe ki a ma ṣe amulo awọn ipese Ọlọrun fun wa lati ṣe bẹẹ? Oun naa ni o ni i ṣe pẹlu yiyẹra fun ibasepọ ti ko dọgba pẹlu awọn alaigbagbọ. Iwọ naa wo ọkan lara awọn nkan ti Pọọlu sọ lori ọrọ yi: “Ki a ma tan yin jẹ: ẹgbẹ buburu ba iwa rere jẹ.” (1Kọrinnti 15:33) Ki ni idi ti o fi nira fun ọpọ lati gbe igbe aye iwa-bi-Ọlọrun loni? Oun naa la ri ninu ọrọ ti Pọọlu sọ silẹ yi. O ni ki a ma ṣe jẹ ki ẹnikẹni tan wa jẹ: ẹgbẹ buburu ma n ba iwa rere jẹ. Eyi jasi pe niwọn igba ti a ba n kọwọ rin pẹlu awọn alaiwa-bi-Ọlọrun, o didan ki awa na ma wuwa bi ti wọn lẹkọkan tabi ni ọpọ igba. Niwọn igba ti a ba si ti n wuwa bi wọn ti ṣe n wuwa, ko si ni ki o ma mu ipalara wa fun igbe aye iwa-bi-Ọlọrun wa.

Pọọlu tun sọ eyi lori ọrọ yi kannaa: “Ẹ ma ṣe fi aidọgba dapọ pẹlu awọn alaigbagbọ: nitori idapọ kin ni ododo ni pẹlu aiṣododo? Idapọ ki ni imọlẹ si ni pẹlu okunkun? Irẹpọ kin ni Kirisiti ni pẹlu Belili? Tabi ipin wo ni ẹni ti o gbagbọ ni pẹlu alaigbagbọ? Irẹpọ ki ni Tẹmpili Ọlọrun ni pẹlu oriṣa? Nitori ẹyin ni tẹmpili Ọlọrun alaaye; gẹgẹ bi Ọlọrun ti wi pe, Emi o maa gbe inu wọn, emi o si maa rin ninu wọn; emi o si jẹ Ọlọrun wọn, wọn o si jẹ eniyan mi.” (2Kọrinnti 6:14-16) 

Ṣe o tun ri bayi? A ki wa nilọ nibiyi pe ki a ma ṣe fi aidọgba dapọ pẹlu awọn alaigbagbọ. Eyi tunmọ si pe ibadapọ pẹlu awọn alaigbagbọ pin si ọna meji pataki. Akọkọ ni ibadọpọ ti o dọgba. Eyi ni i ṣe pẹlu ibaṣepọ wa pẹlu awọn alaigbagbọ ti o jẹ obi wa, ọmọ wa, aya wa, ọkọ wa, ara wa, ibatan wa, aladugbo wa, ọga wa nibi iṣẹ, akẹgbẹ wa nibi iṣẹ tabi ni ile-iwe ati bẹẹbẹẹ lọ. A ko le sọ wipe a ko ni ni nkankan ṣe pẹlu awọn eniyan yi nitoripe alaigbagbọ ni wọn. A gbọdọ ni nkan ṣe pẹlu wọn, ki a si ma ṣe ojuṣe wa lori wọn ni gbogbo igba. Ayafi ti a ba fẹ fi aye yi silẹ nikan ni a ko ṣe ni ni nkankan ba awọn ẹni wọnyi ṣe papọ. (Wo: 1Kọrinnti 5:10)

Irufẹ ibadapọ keji ti a le ni pẹlu awọn alaigbagbọ, eyi ti a si n kilọ fun wa ninu bibeli pe ki a ma ni, ni ibapadọ aidọgba. Ki ni idi ti a si ṣe n kiwa nilọ pe ki a ma ni irufẹ ibadapọ yi pẹlu wọn? Idi ni pe nigba ti a wa jẹ ododo, awọn je aiṣododo. Nigba ti awa si jẹ imọlẹ, awọn jẹ okunkun. Bẹẹ si ni, nigba ti awa jẹ Kirisiti, awọn jẹ Belili. Eyi lo wa tunmọ si pe, ni akọkọ, ibaṣepọ yowu ti a o ni pẹlu awọn alaigbagbọ ti yoo sọ wa di alaiṣododo si Ọlọrun tabi si eniyan jẹ eyi ti a gbọdọ yẹra fun. 

Nkan ti a n sọ ni pe niwọn igba ti ibaṣepọ wa pẹlu alaigbagbọ kan tabi omiran tabi awọn eto tabi irinṣẹ ti wọn gbe kalẹ ba ti jẹ eyi ti ko ni jẹ ki a jẹ olotitọ ni sisin Ọlọrun tabi si awọn eniyan, yala awọn ẹbi wa ni, ijọba ni, ijọ Ọlọrun ni, akẹgbẹ wa ni tabi aladugbo wa ni, ko tọna. A si gbọdọ fi opin si, ti o ba jẹ wipe o ti n waye. Aijẹbẹ, a ko ni le gbe igbe aye iwa-bi-Ọlọrun. 

Nkan keji ti ọrọ yi tun fi ye wa ni pe ibadapọ yowu ti a le ni pẹlu awọn alaigbagbọ ti o si le sọ imọlẹ wa di okunkun jẹ eyi ti ko gbọdọ waye rara. Bẹẹni ibadapọ yowu ti a le ni pẹlu wọn ti yoo jẹ ki a bẹrẹ si ni ṣe nkan ikọkọ tabi ti ko ni jẹ ki a le ba wọn wi ninu aiwa-bi-Ọlọrun wọn jẹ eyi ti a ko gbọdọ jẹ ki o waye. Nitori irufẹ awọn ibaṣepọ yi ni o ma n sọ ọmọ Ọlọrun di ẹlẹṣẹ nikẹyinkẹyin.

Nkan ẹkẹta ti ọrọ Pọọlu tun n fi ye wa ni pe ibadapọ yowu ti a le ni pẹlu awọn alaigbagbọ ti ko ni jẹ ki a le ṣe iyatọ wa si wọn, ti ko ni jẹ ki awọn eniyan mọ pe ti Kirisiti ni a jẹ ati pe a ko ki i ṣe ti Eṣu jẹ eyi ti a ko gbọdọ faye gba. Ibadapọ aidọgba ni. O si wa ṣe ni laanu loni pe ọpọ awọn ọmọ Ọlọrun ni a ko le ṣe iyatọ laarin wọn ati awọn alaigbagbọ ti wọn jọ n ko ara wọn kaakiri. Idi si ni pe aguntan wọn ti ba aja rin, o si ti jẹ ìgbẹ́, o ti ba ẹkùn rin, o ti wọ ẹ̀wù ẹ̀jẹ̀. 

Lotitọ, kíkọ̀ lati ni ibaṣepọ aidọgba pẹlu awọn alaigbagbọ le ma ba irọrun de. O tilẹ le fi aye silẹ fun inunibini lati ọdọ wọn. Ṣugbọn ti ibaṣepọ ayeraye ti a ni pẹlu Ọlọrun ba jẹ wa logun, a gbọdọ fi ara da ohun yowu ti o ba ti ẹyin kíkọ̀ lati fi aidọgba lo pọ pẹlu awọn alaigbagbọ le mu lọwọ. Aijẹbẹ, gbogbo awọn iwa palapala, iwa omugọ ati iwa eeri ti a ti kọ silẹ nitoripe a jẹ ti Jesu ko ni ṣalai tun ma ma fi ara han ninu aye wa.

ỌRỌ IPARI

Ti a ba fẹ ṣe aṣẹyọri ni gbigbe igbe aye iwa-bi-Ọlọrun, a gbọdọ yẹra fun fifi aidọgba ba awọn alaigbagbọ ti o wa ninu aye wa tabi ni ayika wa lopọ. Eyi ni yoo fi iyatọ han laarin awa ati awọn. Aijẹbẹ, ibaṣepọ wa pẹlu wọn ko ni ṣai pa igbe aye iwa-bi-Ọlọrun wa lara.

IBEERE

Irufẹ ibadapọ melo ni a le ni pẹlu awọn alaigbagbọ? Darukọ wọn.

Ki ni o ṣe pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2022,  Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ọ̀NÀ LÁTI TỌ́ ARA RẸ SÍ ÌWÀ-BÍ-ỌLỌ́RUN (2) | Pst. J.O Lawal |TÍMÓTÌ 4:7-11 | ỌJỌ́RÚ 25, ÈBÌBÍ 2022 Read More »

Tun àfojúsùn rẹ ṣe | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbí 29, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 4

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ miran ninu ọdun yi, eyi ti i ṣe ọsẹ ti o so oṣu Èbìbí ati Òkúdù pọ mọ ara wọn. Mo si gbadura pe ki ọkan rẹ ma fi igba gbogbo gba okun lati mu iṣẹ-iranṣẹ yowu ti Ọlọrun gbe le ọ lọwọ ninu ijọba rẹ ni ọkunkundun, ki o ma ba ja a kulẹ, ki o si tun padanu ere rẹ. Amin.

Jesu Oluwa wa ni igba kan ri sọ eyi fun awọn ọmọ ẹyin rẹ: “Ounjẹ mi ni lati ṣe ifẹ ẹni ti o ran mi, ati lati pari iṣẹ rẹ.” (Jòhánù 4:34) Ni akoko miran ẹwẹ, O tun sọ eyi naa fun wọn: “Emi ko le ṣe alaiṣe iṣẹ ẹni ti o ran mi, nigba tii ṣe ọsan: oru n bọ wa nigba ti ẹnikan ki yoo le ṣe iṣẹ mọ.” (Jòhánù 9:4) Ki ni idi ti Jesu Oluwa wa fi sọrọ bi eyi? Lakọkọ, O sọ eyi nitoripe O mọ pe Ọlọrun gbe iṣẹ-iransẹ kan le Oun lọwọ lati gbe ṣe ninu aye yi. Ekeji, O ṣọ eyi nitoripe O mọ ojuṣe rẹ ni ojuṣe rẹ. Eyi lo si jẹ ki O mu iṣẹ iranṣẹ ti Ọlọrun fun ni ọkunkundun. Ẹkẹta, O sọ awọn nkan wọnyi nitoripe O mo wipe Oun ko ni gbogbo ayeraye lati ṣe iṣẹ ti Ọlọrun gbe fun un. Nitorina, ti ko ba gbajumọ iṣẹ naa, ki O si ṣe ni ‘ohun tí ó bá gbà ni a ó fún’, ko ni pari iṣẹ naa titi akoko rẹ ni aye yi yoo fi pari.

Ni bakanna, ẹnikọọkan wa naa ti gba iṣẹ iranṣẹ kan tabi omiran ni ọwọ Oluwa. Ẹnikọọkan wa ni o ni iṣẹ kan tabi omiran ti Ọlọrun ti yan fun un lati ṣe fun ati fun ijọba rẹ ni aye yi. Nkan ti bibeli ṣọ fun wa ni eyi. O wa ku si ọwọ wa lati mọ irufẹ iṣẹ-iranṣẹ ti a ti rigba lọwọ rẹ, ki a si bẹrẹ si ni ṣe pẹlu ifarabalẹ ati pẹlu imura lati pari rẹ ni akoko. Pọọlu, nigba ti o n ba awọn alagba ijọ Efesu sọrọ lori awọn nkan wọnyi, sọ eyi nipa ara rẹ: “Ṣugbọn emi ko ka ẹmi mi si nnkan bi ohun ti o ṣọwọn fun mi, ki emi ki o baa le fi ayọ pari ire-ije mi ati iṣẹ-iranṣẹ ti mo ti gba lọdọ Jesu Oluwa, lati maa royin iyinrere oore-ọfẹ Ọlọrun.” (Iṣe Apọsiteli 20:24)

Ṣe o ti wa ri pe afojusun ti Pọọlu ni fun aye rẹ ko yatọ rara si eyi ti Jesu Oluwa wa ni fun aye tirẹ naa? Afojusun Pọọlu naa ni fun lati ṣe ifẹ Ọlọrun pẹlu aye rẹ ati lati pari iṣẹ rẹ. Njẹ eyi yoo wa rọrun fun bi? Ko lero pe yoo rọrun fun oun. O tilẹ sọ wipe Ẹmi Mimọ ti kilọ fun oun tẹlẹ pe ki oun ma lero pe yoo rọrun fun oun (Ìṣẹ Àpọ́sítélì 20:22-23). Sibẹsibẹ, boya o rọrun fun o tabi ko rọrun fun, o pinnu lọkan rẹ lati ṣe ifẹ Ọlọrun pẹlu aye rẹ ni gbogbo ọna ati lati fi ifarabalẹ pari iṣẹ ti O gbe fun. Ki si ni idi? Idi ni pe o mọ wipe ẹni ti o pe oun, ti o si ya oun sọtọ fun ara rẹ yo ma fi igba gbogbo wa pẹlu oun ati pe yoo ri daju pe oun ṣe aṣeyọri.

Wayi o, ti awa naa ba mura lati rin pẹlu afiyesi ti Jesu Oluwa wa ati Pọọlu ni nipa gbigbe aye wa fun Ọlọrun ati ṣiṣe iṣẹ rẹ, ko si bi a o ṣe ja Ọlọrun kulẹ, bi o ti wu ki nkan le to tabi bi o ti wu ki nkan ma rọrun fun wa to. Amọ ṣe irufẹ ọkan ti a fi n gbe aye niyi bi? Njẹ a n gbe aye pẹlu afiyesi pe o yẹ ki a fi aye wa jin lati dun Ọlọrun ninu ati lati ṣe iṣẹ ti o gbe fun wa, iṣẹ yowu ti o le jẹ ati asiko yowu ti aye wa le wa?

Ti a ko ba ma rin pẹlu afiyesi yi, a kan n fi aye wa ṣofo ni. Lotitọ, o le ma dabi pe a n fi aye wa ṣofo, paapaa julọ ti awọn eniyan ba n yin wa fun awọn aṣeyọri ti a ti ṣe ni awọn abala aye wa kan. Ṣugbọn akoko n bọ, bi o ti ṣe de ba Jona, ti a o ri daju ṣaka pe inu ikun ẹja n la kan, ni inu okunkun birimu-birimu, nibi ti ko ti si èrè, nibi ti ko ti si oriyin, ni gbogbo ere ti a n sa lodi si ifẹ Ọlọrun yoo pari si. Igba yi gan ni a o to wa mọ pe asan lori asan ni gbogbo nkan ti a ti fi aye wa gbe ṣe. Adura mi wa ni pe ki ere-ije rẹ ati laalaa rẹ ninu aye yi ma ja si asan ni ikẹyinkẹyin, ni orukọ Jesu. Amọ iwọ naa gbọdọ tun afojusun rẹ ṣe, ti o ba mọ pe ko da lori bi iwọ yoo ṣe ṣe ifẹ Ọlọrun, ki o si pari iṣẹ ti O gbe fun ọ.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Tun àfojúsùn rẹ ṣe | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbí 29, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 4 Read More »

Má sọ ààyè rẹ nù

Ó burú jọjọ bí kò tilẹ̀ jẹ́ tuntun | J.O. Lawal


LTP-Ebibi-2022_11_3

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ebibi 2022. Mo gbadura pe ki iwọ ati ohun gbogbo ti o jẹ tirẹ ma fi gbogbo igba wa ni ipamọ kuro ninu gbogbo erongba ati akitiyan ibi awọn ọta ẹsin Kirisitiẹni, ni orukọ Jesu. Amin.

Ni aipẹ yi, igbe-rara jade lọ lati ibi gbogbo ni orilẹ-ede yi lodi si ipakupa ti a pa Debora Yakubu Samuẹli, ọmọ ile-iwe giga ti awọn olukọ kan ti o wa ni ipinlẹ Sokoto. Bi iṣẹlẹ yi ṣe wa buru jọjọ to, ti o si jẹ eyi ti a gbọdọ bu ẹnu atẹ lu pẹlu, ko jẹ tuntun tabi ajeji si aye yi. Irufẹ awọn iṣẹlẹ bẹẹ ti ṣẹlẹ sẹyinsẹyin, bi wọn si tun ti ṣe n ṣẹlẹ lọwọlọwọ yi kaakiri gbogbo agbaye, paapaa-julọ ni awọn ibi ti awọn eniyan ti ro pe ojuṣe wọn ni lati gbe Ọlọrun nija tabi lati da aabo bo iyi rẹ.

Njẹ o tilẹ mọ pe ni abẹ idari awọn alufa ijọ Katoliki mimọ ti Roomu, ni ọgọọgọrun ọdun sẹyin, ọpọlọpọ awọn eniyan rere ati olododo eniyan ni a sọ ni okuta pa, ti a ge lori tabi ti a dana sun laitọ nitori isọrọ-odi tabi isọkusọ? Nitorina, ti ijọ ko ba pa awọn ọmọ rẹ mọ loni, ko ki i ṣe nitoripe ko lailai ṣe bẹẹ ri; dipo eyi, o je nitoripe Ẹmi Ọlọrun ti fọ ọ mọ kuro ninu aimọkanmọkan rẹ, ti O si tun ti tun un ṣe.

Siwaju si, ko yẹ ki a gbagbe pe idi ti awọn adari ẹsin Juu ti igba aye Jesu fi pa a nipa ika. Nitori isọrọ-odi ni. Awọn Juu wọnyi, bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ko fi aye gba isọrọ-odi rara-rara. Nitorina, nigba ti Jesu bẹrẹ si ni pe ara rẹ ni ọmọ Ọlọrun, wọn ṣiro ọrọ rẹ si isọrọ-odi, wọn si bẹrẹ si ni bere fun ori rẹ. Ṣugbọn awọn adari wọn ko kan dede ki i mọlẹ ni oju ọna, ki wọn si pa a, bi awọn ọgọrọ eniyan ti inu n bi yoo ti ṣe. Dipo eyi, nṣe ni wọn mu, wọn wa awọn ti yoo jẹri lodi si, wọn si wa da ẹjọ iku fun.

Ki wa lo de ti wọn ko pa Jesu fun isọrọ-odi lẹsẹkẹsẹ ti wọn ti ri mu? Akọkọ, idi ni pe wọn mọ pe ọpọ ni ilẹ naa ni o gbagbọ pe eniyan Ọlọrun tootọ ni Jesu jẹ. Nitori eyi, ti ko ba wa jẹ pe a fi idi rẹ mulẹ daju pe O ṣe nkan èèwọ̀ kan, bi ki O sọ ọrọ odi si Ọlọrun, wọn ko le nawọ gan lailai ba ibinu awọn eniyan pade. Ka tilẹ tun gbe iyẹn sẹgbẹ kan, o lodi si ofin Mose lati pa ẹnikẹni lọna yi lalai ṣe pe a kọkọ gbọ ẹjọ rẹ lọna ti o yẹ. A kọkọ gbọdọ wa o kere ju ẹlẹri meji lati jẹri lodi si. Lẹyin eyi, a gbọdọ fi aye gba oun naa funrarẹ lati wi àwíjàre. Aijẹbẹ, nṣe ni a o ma ta ẹjẹ alaiṣẹ silẹ niwaju Ọlọrun ti a ba pa a. Bẹẹ gẹgẹ si ni a ṣe ṣe si Jesu ki a to da ẹjọ iku fun un lọna aitọ. (Wo: Ditaronomi 17:2-7; Matiu 26:57-66)

Idi keji ti a ko fi pa Jesu ni ẹsẹkẹsẹ ti a mu ni pe ofin miran ti o tun ga ju ti Mose lọ wa ni ilẹ naa nigba naa, iyẹn ofin awọn ara Roomu. Ko si wa si bi wọn yoo ṣe pa gbajumọ eniyan bi ti Jesu, bi O tilẹ jẹbi ẹsun ti a fi kan an, lalai ṣe pe wọn kọkọ gbọ ẹjọ rẹ ni ibamu pẹlu ofin yi, ti wọn ko ni bọ sinu iyọnu ti awọn adari ijọba Roomu ti o wa lori wọn ba mura lati ṣe agbeyẹwo ọrọ naa. Idi niyi ti a ṣe mu Jesu lọdọ sọdọ Pọ́ntíù Pílátù, ki o ba le fi ountẹ jan ẹjọ iku ti a ti da fun un. A ko ba wi wa tu u silẹ, ti ko ba jẹ wipe Pilatu jẹ adari ojo ati kòṣekukòṣẹyẹ kan. (Wo: Johanu 18:26-19:16)

Nitorina, ko ki n ṣe nkan tuntun ni ki a pa awọn olododo laitọ labẹ afiboju ẹsin. Iru nkan wọnyi si ma n ṣaba waye nibi ti awọn adari ba ti jẹ ojo bi ti Pilatu, ti wọn si tun fẹran iyin awọn eniyan ju iyin Ọlọrun lọ. Fun apẹẹrẹ, Pọọlu gan, ni akoko kan, ko ba di ẹni ti ọgọrọ awọn Juu kan ti inu n bi ko ba faya pẹrẹpẹrẹ nitori iru ọrọ yi, ti o ba jẹ pe ọgagun awọn jagunjagun Roomu ti a fi si Jerusalẹmu ni akoko yi jẹ ojo tabi lọra lati tete da si ọrọ naa. (Wo: Iṣe Apọsiteli 21:17-23:35)

Ki ni koko ti mo fẹ mu jade lori ọrọ yi? Oun naa ni pe bi a ti ṣe n bere fun idajọ ododo fun Debora Yakubu Samuẹli ati ti a si tun n gbadura pe ki Ọlọrun tu awọn ẹbi rẹ ninu, a ko gbọdọ kuna, gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun, lati kẹkọ lati ara nkan ti o ṣẹlẹ si. Ki si ni awọn ẹkọ fun wa ninu ọrọ naa? Akọkọ ni pe a gbọdọ ma fi gbogbo igba ṣọ ara ṣe ninu ibaṣepọ wa pẹlu awọn ẹlẹsin miran, paapaa-julọ awọn ti o korira ẹsin Kirisitiẹni, ki wọn ma ba fi akoko kankan ni idi ti o daju lati sọrọ odi si wa tabi lati da wa lẹbi.

Ẹkọ keji fun wa ninu ọrọ yi ni pe nibikibi ti iṣedari ibi ti a n gbe ba ti jẹ ojo tabi alailootọ, Ọlọrun le ma le lo o lati da aabo bo wa kurọ lọwọ iwa ika. Nitorina, ti ko ba jẹ wipe a mọ daju pe Ọlọrun fẹ lo ijiya tabi iku wa nibẹ lati ṣe ara rẹ logo, a gbọdọ ṣọra ṣe ni didasi ohunkohun ti o ba ni i ṣe pẹlu ọrọ ẹsin nibẹ. Aijẹbẹ, o ṣeeṣe ki a sun ninu Kirisiti ki akoko wa to to. Njẹ ki Ọlọrun gbogbo oore-ọfẹ tẹsiwaju lati ma pa gbogbo awọn ọmọ rẹ ni orilẹ-ede yi ati ni ibi gbogbo lagbaye mọ kuro lọwọ ibi gbogbo. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ tí ó ga.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ó burú jọjọ bí kò tilẹ̀ jẹ́ tuntun | J.O. Lawal Read More »

Ǹjẹ́ ọkàn rẹ ṣe déédé níwájú rẹ̀ bí? | Pst. J.O. Lawal | Èbìbí 15, 2022 | Vol. 11, No. 2

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo ki ọ kaabọ sinu ọṣẹ miran ninu oṣu yi. Mo si tun gbadura pe ki Ọlọrun ṣe ọkan rẹ yẹ niwaju rẹ ni gbogbo igba, ki eré-ìje Kirisitiẹni rẹ ninu aye yi ma ba ja si asan. Amin.

Ninu iwe Iṣe awọn Apọsiteli, a ri akọsilẹ arakunriin kan ti a n pe ni Simoni Oṣó. Ọkunrin yi, bi akọsilẹ naa ti ṣe lọ, je olugbe ilu awọn ara Samaria kan ti Filipi ti kọkọ waasu ihinrere Jesu Kirisiti. Nigba ti o si ri awọn iṣẹ iyanu ati ara ti ajinhinrere yi ṣe, ẹnu yaa to bẹẹ gẹẹ ti oun naa fi ṣe iribọmi ni orukọ Oluwa bi awọn ara Samaria yoku ti o wa ninu ilu yi. (Ìṣe Àpọ̀sítélì 8:5-24) 

Ṣugbọn oṣo ni ọkunrin yi jẹ, oṣo ti o ti fi akoko kanrí jọ awọn eniyan wọnyi loju pẹlu agbara àlùpàyídà ati oṣo rẹ. Nitorina, nipa ṣiṣe iribọmi ni orukọ Jesu, o n fihan pe oun gba pe Filipi n ṣiṣẹ pẹlu agbara ti o ga, ti o si pọ ju ti oun lọ. Eyi si jẹ nkan ti gbogbo ọmọ Ọlọrun gbọdọ fi sọkan. A n ṣiṣẹ pẹlu agbara ati aṣẹ ti o ga julọ ni ibi yowu ti awọn ẹda Ọlọrun le wa. Nitori eyi, nṣe ni o yẹ ki a gbe gbogbo ibẹru iṣẹ awọn ajẹ, oṣo ati alafọsẹ ti a ni ju ṣọnu. Bẹẹni, nṣẹ ni o yẹ ki a gbe gbogbo ibẹru Eṣu ati awọn ẹmi aimọ rẹ ti a ni ju danu. Idi si ni pe a ni aṣẹ ati agbara lori wọn ninu Kirisiti Jesu – abẹ atẹlẹṣẹ wa ni gbogbo wọn wa. (Wo: Luuku 10:19; Roomu 16:20; 1Johanu 2:14; 1Johanu 4:4)

Ni kukuru, lẹyin igba ti o ti ṣe iribọmi ni orukọ Jesu, Simoni bẹrẹ si ni tẹle Filipi lọ si ibikibi ti o ba lọ, nitoripe awọn iṣẹ ami ati iṣẹ iyanu ti o n ri jọ ọ loju pupọ. Eyi tunmọ si pe oun naa bẹrẹ si ni ṣe bi ọmọ Ọlọrun, bi Kirisitiẹni tootọ. Ṣugbọn nigba ti awọn Apọsiteli Peteru ati Johanu de si ilu kannaa yi, ti wọn si bẹrẹ si ni gbe ọwọ le awọn ti o gbagbọ lori lati gba Ẹmi mimọ, ete ibi inu ọkan Simoni farahan.

Ki gan an lo ṣe? O gbiyanju lati fun wọn ni owo lati rẹ ẹbun Ẹmi mimọ. Ki si ni idi? Idi ni pe oun naa fẹ maa ṣe ohun ti Filipi ati awọn apọsiteli yi n ṣe. O si ni itara lati ṣe to bẹẹ gẹẹ ti o fi ṣetan lati fi owo ra agbara lati ṣe bẹ ẹ. Nitorina, ko jẹ tuntun lati ri awọn eniyan ti wọn ṣetan lati gbe igbesẹ-ki-gbesẹ, pẹlupẹlu didara pọ mọ ẹgbẹ okunkun tabi lilo afọsẹ ati ẹmi oṣo, ti yoo jẹ ki wọn le ma jọ awọn eniyan loju, ki wọn si ma fi ara wọn han gẹgẹ bi eniyan pataki ninu ijọba Ọlọrun.

Bawo wa ni Peteru ṣe fesi si nkan ti Simoni ṣe? O da lohun nipa sisọ awọn ọrọ wọnyi:

“Ki owo rẹ ṣegbe pẹlu rẹ, nitori iwọ ro lati fi owo ra ẹbun Ọlọrun. Iwọ ko ni ipa tabi ipin ninu ọran yii: nitori ọkan rẹ ko ṣe deedee niwaju Ọlọrun. Nitori naa ronupiwada kuro ninu iwa buburu rẹ yii, ki o si gbadura sọdọ Ọlọrun, boya yoo dari ete ọkan rẹ ji ọ. Nitori ti mo woye pe, iwọ kun fun owu kikoro, ati wi pe ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ ni iwọ n ṣe.”

Njẹ o ri bayẹn? Ki ni iṣoro ti Simoni ni? Ohun naa ni pe ọkan rẹ ko ṣe deede pẹlu Ọlọrun. Ko fi igba kankan di atunbi ni tootọ. Ko fi igba kankan ni ipa ninu Kirisiti. Ẹ si wa wo o, o n ṣe wọle-wọde pẹlu Filipi ati awọn apọsiteli yi o. O sun mọ wọn pẹkipẹki, o si tun jẹ igbadun ibaṣepọ pẹlu wọn. O tilẹ ṣeeṣe ki o ti ba wọn jẹun papọ ni awọn igba kan tabi ki o ti ba wọn jẹ awọn iṣẹ kọọkan ri. Sibẹsibẹ, ọkan rẹ ko ṣe deede.

Nitorina, pe o n wa si ipade ijọ loorekoore tabi pe o n ṣe wọle-wọde pẹlu awọn oniwasu ati awọn onigbagbọ kan tabi omiran ko tunmọ si pe ọkan rẹ ṣe deede. Lotitọ, awọn eniyan le ma mọ nkan ti o n lọ ninu ọkan rẹ, ti a ko ba fi han wọn, bi a ti ṣe niti Simoni. Wọn le ma mọ pe o kun fun owu, ojukokoro, idibajẹ ati ẹtanu. Ṣugbọn Ọlọrun mọ. Iwọ naa si mọ pẹlu. Ti o ko ba si ronupiwada lakoko ti o tọ, ọjọ kan le de ti awọn iṣẹlẹ kan yoo tu aṣiri ete eke ati ika inu ọkan rẹ.

Yatọ si iyẹn, niwọn igba ti ọkan rẹ ko ba ti ṣe deede niwaju Ọlọrun, bi o tilẹ jẹ atunbi ni tootọ, o di dandan ki o pa iriri didara Ọlọrun ti o yẹ ki o ni lara. Eyi si ni alaye fun bi igbega, iwosan, isesorere, ibalẹ-ọkan ati iṣoriire ti awọn onigbagbọ kan n wa ko ni lailai jẹ ti wọn. Ọkan wọn ko ṣe deede. Ti wọn ko ba si ronupiwada, ko si ni ki nkan ma bajẹ ju bayi lọ fun wọn. Nitori eyi, ṣọ kan rẹ pẹlu ìfarabalẹ̀ ti o ga, ki o si tun ti ilẹ̀kuǹ rẹ̀ mọ́ ojukokoro, ẹtanu, owu ati èrò ìkà gbogbo. Ki Ọlọrun oore-ọfẹ jẹ ki o le ma fi gbogbo igba ṣe eyi fun anfaani ara rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ǹjẹ́ ọkàn rẹ ṣe déédé níwájú rẹ̀ bí? | Pst. J.O. Lawal | Èbìbí 15, 2022 | Vol. 11, No. 2 Read More »

Kí ni ìwọ ń ṣe níhìn-ín | Pásítọ̀ J.O. Lawal

Ọjọ́: Èbìbí 08, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 1

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Kaabọ sinu osẹ tuntun miran ninu oṣu Èbìbí 2022. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ri daju pe a fi idi rẹ mulẹ si ibugbe ti o tọ fun ete rẹ lati wa si imu ṣẹ ninu aye rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ni igba kan ri, Ọlọrun fi ara han Wolii Elija ni ori oke Horẹbu, O si bere ibere nla yi lọwọ rẹ lẹẹmeji: “Kini o n ṣe nibiyi?” Wayi o, igba wo ni a ma n bere iru ibere yi lọwọ eniyan? Akọkọ, a ma n bere rẹ lọwọ wọn nigba ti a ko ba reti lati ri wọn ni ibi ti a ti ri wọn, ti o si jẹ wipe ibomiran ni a n woye pe o yẹ ki wọn wa. Ẹkeji, a ma n bere rẹ lọwọ wọn nigba ti a ba fẹ mọ nkan ti wọn n ṣe nibi ti wọn wa ati ti a ba fẹ ẹ mọ boya nkan naa ti wọn n ṣe nibẹ to lati mu wa si ibẹ tabi duro si ibẹ.

Nitorina, nigba ti Ọlọrun bere lọwọ Elija pe, “Ki ni iwọ n ṣe nihin-yin?” akọkọ, O fẹ ki o mọ pe Oun ko reti lati ri nibẹ ni akoko naa. Ẹkeji, O fẹ mọ nkan ti o ba wa si ibẹ. Ṣe ko wa mọ nkan ti o ba wa sibẹ ni? O mọ ọn. Ṣibẹsibẹ, O fẹ ti ẹnu oun tikararẹ gbọ. (Wo: 1Ọba 19)

Kama fa ọrọ gun, idi yowu ti Elija fi wa ni Horẹbu ni akoko yi ko ja mọ nkankan si Ọlọrun. Idi si nipe ko yẹ ki o tilẹ wa nibẹ rara. Lotitọ, idamu aye ni o ti lọ si ibẹ lati tọrọ fun iku. Ṣugbọn ko yẹ ki o wa ni ibẹ. Idi si ni pe iṣẹ rẹ laye ko i ti pari. Nitorina, Ọlọrun sọ fun pe ki o gba ọna ti o gba wa pada lati lọ pari iṣẹ rẹ. O si ṣe bẹẹ gẹgẹ.

Ni ọna kanna, a ri awọn eniyan loni ti o wa ni ibi ti ko tọ ki wọn wa ni aye. Eyi si ni idi ti wọn ko ṣe gberu si tabi ri imuṣẹ ete Ọlọrun lori aye wọn. Lotitọ, bi Elija tabi Haga, iranṣẹbirin Sara, idamu aye ni o le wọn kuro ni ibi ti Ọlọrun fẹ ki wọn wa lọ si ibi ti ko yẹ ki wọn wa. Ṣibẹsibẹ, bi o ti wu ki ara tu wọn to ni ibi to ko tọ fun wọn lati wa ti wọn si wa yi, ete Ọlọrun ko le wa si imuṣẹ lori aye wọn lẹkunrẹrẹ. (Wo: Jẹnẹsisi 16)

Nitorina, wọn nilo lati ri nkan wọnyi, ki wọn si kuro ni ibi ti wọn wa lọ si ibi ti Ọlọrun fẹ ki wọn wa. Oun gan si ti wa n kọ si wọn pe, “Ki ni oun ṣe nibi ti o wa yi? Njẹ o mọ wipe ko yẹ ki o wa ni ibi yi? Njẹ o mọ wipe ete ati ileri mi fun ọ ko le wa si imuṣẹ nibi ti o wa yi?” Amọ ṣe wọn tilẹ le gbọ ohun rẹ? Ti wọn ba si le gbọ, ṣe wọn ṣetan lati gbera lati ibi ti wọn wa lọ si ibi ti o fẹ ki wọn wa, ki wọn ba le ri ààyè lati gberu ati lati ni iriri imuṣẹ ete rẹ rere fun wọn?

Boya iwọ naa si wa jẹ ọkan lara irufẹ awọn eniyan yi. Adura mi fun ọ ni pe ki Ọlọrun ṣi eti rẹ lati gbọ ohun ti o n sọ fun ọ, ki O si tun fun ọ ni okun lati gbe igbesẹ ni ibamu pẹlu rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ ìtura.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Kí ni ìwọ ń ṣe níhìn-ín | Pásítọ̀ J.O. Lawal Read More »