June 2022

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ TẸSALÓNÍKÀ KÍNNÍ | AYỌKA: 1TẸSALÓNÍKÀ 2:17-3:13

ÀKỌ́SÓRÍ: “”Nitori ẹyin tikarayin mọ, ara, pe ibẹwo wa si yin kii ṣe lasan.” (1Tẹsalonika 2:1)

Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ Ninu ẹkọ ti a kọ ṣẹyin ninu lẹta Pọọlu si ijọ Ọlọrun ti o wa ni Tẹsalonika, a ri daju wipe iha ti a ba kọ si ọrọ Ọlọrun ti a mu tọ wa wa ati si iṣẹ iranṣẹ awọn ti a ba ran si wa ni ipa ti o ga lati ko lori igbala ati idagbasoke wa ninu ẹmi. Gẹgẹ bi Pọọlu ti jẹ ki o ye wa ninu lẹta yi, awọn ara Tẹsalonika yi tẹwọgba ọrọ Ọlọrun ti a mu tọ wọn wa gẹgẹ bi ọrọ rẹ tootọ. Wọn ko foju tẹnbẹlu rẹ bi ọrọ lasan tabi ọrọ ẹlẹran ara. Idi si ni yi ti ọrọ naa ṣe bẹrẹ si ni ṣiṣẹ ninu aye wọn, ti o si n so eso rere nibẹ (1Tẹsalonika 2:13). Eyi si n jẹ ki o ye wa pe ti awa naa ko ba ri ọrọ Ọlọrun ti o n tọ wa wa gẹgẹ bi ọrọ eniyan ṣugbọn bi ọrọ rẹ, o di dandan ki o ṣiṣẹ gidigidi ninu aye awa naa, ki o si so eso ti o yẹ ki o so. Amọ niwọn igba ti a ko ba ti kọbiara si ọrọ rẹ tabi ti a ri bi ọrọ lasan, aye wa ko ni gba iyipada ọtun ti o yẹ ki o gba. Pataki lara awọn nkan ti yoo si jẹ ki a gba ọrọ Ọlọrun bi o ti ṣe tọ ati bi o ti ṣe yẹ ni ki a gba awọn iransẹ rẹ ti O n ra si wa gẹgẹ bi iranṣẹ rẹ tootọ. Ti a ko ba gba wọn gẹgẹ bi iransẹ rẹ, yoo nira fun wa lati gba ọrọ yowu ti wọn ba n sọ fun wa gbọ. Yoo si tun nira fun wa pẹlu lati fi aye gba iṣẹ yowu ti Ọlọrun ba fẹ tipasẹ wọn ṣe fun wa. Idi kan gbogi si ni yi ti ọpọ ko ṣe ni itẹsiwaju ninu irin-ajo igbagbọ wọn, ti wọn ko si ma gbadun Ọlọrun bi o ti ṣe tọ ati yẹ. Ti wọn ko ba si ronupiwada, ki wọn si bẹrẹ si ni kọ iha ti o tọ ati ti o yẹ si iṣẹ iranṣẹ awọn ti a ran si wọn ati si ọrọ Ọlọrun ti wọn n mu tọ wọn wa, aye wọn ati irin-ajo igbagbọ wọn ko ni lọ bi o ti ṣe yẹ ki o lọ.

PÀTÀKÌ MÍMỌ IPÒ ÀWỌN ỌMỌ ỌLỌ́RUN

Bi a ti ṣe wa ri ninu lẹta Pọọlu yi, aye awọn ọmọ ijọ Tẹsalonika n lọ bi o ti ṣe yẹ ki o lọ ninu irina-ajo igbagbọ wọn pẹlu Kirisiti Jesu, bi o tilẹ jẹ wipe awọn apọsiteli yi ko duro pẹ lọdọ wọn. Bawo ni wọn ṣe wa mọ pe aye awọn onigbagbọ yi n lọ bi o ti ṣe yẹ ki o lọ nigba ti o jẹ wipe wọn ko si pẹlu wọn? Nipasẹ Timoti, ẹni ti o ṣe ibẹwo si wọn, ni wọn ṣe mọ. Eyi tilẹ wa jẹ ki Pọọlu mẹnuba diẹ lara pataki ki gbogbo wa ti a jẹ ọmọ Ọlọrun, paapaa julọ awọn adari wa, ma fi gbogbogb igba mọ ipo awọn ọmọ Ọlọrun ti a jọ n jọsin papọ, ti a jọ n gbe papọ, ti wọn jẹ ẹbi wa tabi ti wọn wa ni abẹ isakoso wa. Gẹgẹ bi o ti ṣe sọ, igba meji ọtọọtọ ni o tikararẹ gbiyanju lati yọju si awọn ara Tẹsalonika yi, lẹyin igba ti inunibini ti jẹ ki wọn kuro ni ilu wọn, ki o ba le mọ ipo wọn. Wo alaye rẹ lori ọrọ yi:

“Ṣugbọn ara, awa ti a ya nipa kuro lọdọ yin fun saa kan nipa ti ara, kii ṣe ni nipa ti ẹmi. Pẹlu ọpọlọpọ itara ni awa ṣe aniyan ti a si fẹ gidigidi lati ri oju yin. Nitori awa fẹ lati tọ yin wa, ani emi Pọọlu lẹẹkinni ati lẹẹkeji, Satani si de wa ni ọna.” (1Tẹsalonika 2:17-18)

Pọọlu ko salaye lẹkunrẹrẹ ninu lẹta yi ọna ti Satani gba di oun ati awọn alabaṣiṣẹ rẹ lọwọ lati yọju si awọn ara Tẹsalonika yi. Ṣugbọn pẹlu nkan ti o sọ yi, a ri daju pe Satani le di ọmọ Ọlọrun lọwọ lati ṣe ifẹ rẹ. O le lo ọ̀dá owo, inunibini, aisan, ijamba, ajalu, ofin ailojutu ati bẹẹbẹẹ lọ lati di wọn lọwọ. Ti a ko ba wọn ni imọ eyi, a ko ni gbe igbesẹ ti o loorin lati doju ija kọ oun ati awọn iṣẹ ibi rẹ pẹlu awọn ohun ija ti Ọlọrun ti fun wa, ki a si rin ni iṣẹgun lori wọn.

Ni kukuru, Satani di Pọọlu ati awọn iyoku rẹ lọwọ lati de Tẹsalonika nitori pe o mọ pataki ki wọn yọju si awọn onigbagbọ yi, ki wọn si mọ ipo ti wọn wa. Ki wa ni pataki ki a mọ ipo awọn onigbagbọ ti o wa labẹ iṣakoso wa tabi ninu aye wa? Lara rẹ ni iwọnyi, gẹgẹ bi Pọọlu ti jẹ ki o ye wa:

– Fun ifẹsẹmulẹ awọn ọmọ Ọlọrun ninu igbagbọ (1Tẹsalonika 3:1-4): Ki a di atunbi kọ ni opin ohun gbogbo ninu irin-ajo Kirisitiẹni; ipilẹ lasan ni o jẹ. Ṣugbọn ọpọ ni eyi ko ye. Nitorina eṣu gba wọn danu lẹyin ti wọn ti di atunbi tan, ko si jẹ ki wọn fi ẹsẹ mulẹ ninu igbagbọ wọn. O wa le jẹ nitoripe wọn ko fi aye silẹ fun awọn ọmọ Ọlọrun ti òye ye lati ṣe amojuto aye wọn ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ ni eyi ṣe waye tabi ki o jẹ wipe awọn ọmọ Ọlọrun ti o wa ninu aye wọn ko ni oye pe ojuṣe wọn ni lati jẹ olutọju fun awọn ara wọn. Amọ òye eyi ye Pọọlu daradara. O mọ wipe oniruuru idojukọ ni awọn ti o ba gbagbọ ninu Jesu yoo ba pade ninu aye yi ati nitori igbagbọ wọn. O si ti tẹnumọ eyi fun awọn ara Tẹsalonika nigba ti o wa lọdọ wọn. Idi niyi ti oun ati awọn alajọṣiṣẹpọ rẹ ṣe lepa pẹlu itara lati yọju si awọn ara yi, ki wọn ba le tu wọn ninu, fi ọrọ Ọlọrun bọ wọn ati fun wọn ni oriya lati ṣe amulo oore-ọfẹ Kirisiti Jesu lati fi ẹsẹ mulẹ ninu igbagbọ wọn, bi o ti wu ki idojukọ ati inunibini ti wọn n ba pade pọ to. Ti awa naa ba fẹ ki awọn ọmọ Ọlọrun ti a jọ n jọsin pọ tabi ti o wa ninu aye wa fi ẹsẹ mulẹ ninu igbagbọ wọn, a gbọdọ ma fi gbogbo igba lepa lati mọ ipo ti wọn wa ati lati ṣe ohun yowu ti Ọlọrun ba fun wa ni oore-ọfẹ lati ṣe ki igbagbọ wọn ba le duro ṣinṣin.

– Ki laala awọn adari tabi olusọ awọn ọmọ Ọlọrun ma ba ja si asan (1Tẹsalonika 3:5-9): Pọọlu ati awọn yoku rẹ ti ṣiṣẹ karakara laarin awọn ara Tẹsalonika ki wọn to fi wọn silẹ. Ṣe o wa yẹ ki laala wọn lori awọn ara yi jasi asan bi? Ṣe o wa yẹ ki wọn de ijọba ayeraye Ọlọrun ki wọn si ma ba awọn eniyan yi nibẹ? Ko yẹ ki o ri bẹ. Ṣugbọn, gẹgẹ bi owe ti o sọ wipe, “Kí ojú má rí ibi, gbogbo ara lòògùn rẹ̀,” ti wọn ko ba gbe igbesẹ lati mọ ipo awọn ara yi, ki wọn si mọ bi wọn ti ṣe n ṣe deede si ninu irin-ajo igbagbọ wọn, o ṣeeṣe ki laala ti wọn ti ṣe lori wọn ja si asan. Idi si niyi ti wọn fi ṣe ran Timoti lati yọju si wọn, nigba ti wọn ri pe ko ṣeeṣe fun gbogbo wọn lati lọ. Ti awa naa ko ba fẹ ki gbogbo laala wa, adura wa, fififunni wa ati awọn ọrọ iyanju wa si awọn ọmọ Ọlọrun ti o wa ninu aye wa tabi ti a fi si abẹ akoso wa ja si pabo, a gbọdọ ri daju pe a mọ bi o ti ṣe n lọ ninu aye wọn ati pe a ko jina si wọn rara. Eyi yoo jẹ ki Ọlọrun le lo wa lati daabo bo wọn kuro lọwọ iṣẹ ati akitiyan Eṣu lati bi wọn lulẹ. Ti a ba wa ṣe ohun gbogbo ti o yẹ ki a ṣe fun awọn eniyan, ti wọn si papa wa ṣegbe, Ọlọrun funrarẹ yoo mọ wipe a ṣe iwọn ti a le ṣe, yoo si pin wa ni ere ti o tọ fun iṣẹ wa. Amọ ṣe a le fọwọ ṣoya pe a n ṣe ohun gbogbo ti o yẹ ki a ṣe ki laala wa lori awọn ọmọ rẹ ma ba ja si asan bi?

– Ki a le mu atunṣe tabi aṣepe ba kudiẹ-kudiẹ yowu ti o ba sọrọ mọ igbagbọ awọn ọmọ Ọlọrun (1Tẹsalonika 3:10): Pe a fi ẹsẹ mulẹ ninu igbagbọ wa ninu Kiristi ko tunmọ si pe a ti di pipe patapata ni iwa, ero, iṣe, iwa-mimọ, ifẹ ati awọn eso tabi ẹbun ẹmi yoku. Nitorina, a nilo ibaṣepọ ti o loorin pẹlu awọn ọmọ Ọlọrun miran bi tiwa, ti awọn naa duro ṣinṣin, ki Ọlọrun ba le ti ipasẹ wọn ṣe aṣepe awọn nkan ti o ku-diẹ-kaato ninu irin-ajo igbagbọ wa. Bi Pọọlu ti ṣe fi ye wa ninu lẹta yi, awọn Ijọ Tẹsalonika jẹ awokọsẹ rere fun gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun ti o wa ni ayika wọn. Idi si ni pe igbagbọ, ifẹ ati ireti wọn ninu Kirisiti Jesu munadoko. Sibẹsibẹ, apọsiteli yi mọ wipe o ṣeeṣe ki a si ri awọn kan lara wọn tabi awọn abala aye wọn kan ti nkan ko ti ṣe deede to ninu irin-ajo igbagbọ wọn. Fun apẹẹrẹ, bi lẹta rẹ keji ti ṣe fi ye wa, a ri awọn ọlẹ ati onimẹlẹ eniyan laarin wọn, awọn ti wọn n titori pe awọn n duro de Jesu kọ lati ṣiṣẹ ati lati wulo fun ara wọn ati fun awọn miran (2Tẹsalonika 3). Nitorina, o ri wipe o ṣe pataki ki oun yọju si wọn lati mọ ipo wọn, ki o ba le mojuto awọn kudiẹ-kudiẹ yowu ti o ba foju gáání ni aarin wọn. Awa naa wa gbọdọ fi eyi ṣe ẹkọ, ki a si ma fi gbogbo igba kiyesi awọn nkan ti a ba woye pe ko dara to ninu aye awọn ara wa, ki a ba le ṣe atunṣe wọn pẹlu ọgbọn Ẹmi mimọ.

– Awọn ọmọ Ọlọrun ti o ba tipasẹ wa duro ṣinṣin yoo jẹ ade ogo ati ayọ fun wa nigba ti Jesu ba de (1Tẹsalonika 2:19-20): Bi o tilẹ jẹ wipe koko yi gan ni Pọọlu kọkọ mẹnuba ninu lẹta yi gẹgẹ bẹ ọkan pataki lari idi ti a ṣe gbọdọ ma fi gbogbo igba mọ ipo awọn ọmọ Ọlọrun ti o wa ni abẹ iṣakoso wa tabi ti o wa ninu aye wa, ki a si ran iduro-ṣinṣin wọn lọwọ, oun ni yoo jẹ iriri ti a o ni kẹyin. Iriri yi ko si ni waye ninu aye yi bikoṣe ninu ijoba ayeraye ti Ọlọrun yoo fi lọlẹ ni akoko tirẹ. Ki ni nkan ti a n sọ? Oun naa ni wipe gbogbo awọn ti Ọlọrun ba lo wa lati jẹ ki wọn duro ṣinṣin ninu igbagbọ de opin ni yoo jẹ ade ogo ati ayọ fun wa nigba ti Jesu ba de. Ọpọ ọmọ Ọlọrun ni o n wa ogo wọn ti o sọnu kaakiri loni nitori pe oye nkan ti a n pe ni ogo ko ye wọn. Fun apẹẹrẹ, ki ni ogo Òrùn? Ogo Òrùn ni ki o tan imọlẹ kaakiri aye. Nitorina, ogo Kirisitiẹni ni ki ó gbe igbe aye ti Ọlọrun fẹ ki o gbe, ki o si ṣe awọn iṣẹ ti O fẹ ki o ṣe lẹkunrẹrẹ. Ara awọn iṣẹ ti O si fẹ ki ó ṣe ni ki ó mojuto awọn ọmọ rẹ ti ó wa ninu aye rẹ tabi ti o wa ni abẹ akoso rẹ, Ti o ba si ṣe iṣẹ yi debi pe awọn eniyan yi de ijoba ayeraye rẹ, o didan ki o ri ere gba lọwọ Ọlọrun. Ere yi ni Pọọlu ati Peteru pẹlu pe ni ade ogo ti ki i ṣa (1Peteru 5:1-4). Njẹ iwọ ha nifẹ si ade yi bi? Ti o ba nifẹ si, ripe o ṣe iṣẹ iranṣẹ rẹ fun iduro ṣinṣin awọn ọmọ Ọlọrun de opin ni aṣepe.

ỌRỌ IPARI

Ni ipari, Pọọlu gba adura pe ki Ọlọrun la ọna ti Satani di fun wọn lati le de ọdọ awọn ara Tẹsalonika yi, ki wọn ba le mu ifẹ rẹ ṣẹ lori aye wọn (1Tẹsalonika 3:11). O si tun gba adura fun awọn ara yi naa pe ki Ọlọrun mu wọn pọ si ninu ifẹ rẹ, ki O si tun fi okun fun ọkan wọn lati wa ni alailabuku ati ni mimọ nigba ti Jesu Oluwa wa ba farahan (1Tẹsalonika 3:12-13). Awa na si gbọdọ kọ lati ma gba irufẹ awọn adura yi. A gbọdọ ko lati ma gbadura pe ki Ọlọrun la ọna fun wa lati ṣe ifẹ rẹ ni igbakigba ti a ba woye pe Satani n gbogun lati di wa lọwọ. A tun gbọdọ ma fi gbogbo igba gba a ladura pe ki Ọlọrun fi okun fun ọkan wa lati wa ni alailabuku ati ni mimọ nigba yowu ti Jesu Oluwa wa ba de. Aijẹbẹ, ipa wa ati akitiyan wa lati ṣe ifẹ rẹ ati lati duro ni pipe niwaju rẹ ni gbogbo igba di dandan ki o ja wa kulẹ.

IBEERE – Ọpọ ọmọ Ọlọrun ni ko ni oye pe Satani le di wọn lọwọ lati ṣe ifẹ Ọlọrun. Ki ni idi?

– Ki ni o ṣe pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ TẸSALÓNÍKÀ KÍNNÍ | AYỌKA: 1TẸSALÓNÍKÀ 2:17-3:13 Read More »

Ọ̀tá ara rẹ | Pst. J.O. Lawal | Òkúdù 26, 2022 | Vol. 11, No. 8

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Tayọtayọ ni mo fi ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o kẹyin oṣu Òkúdù 2022. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ya aye rẹ ya ohun gbogbo ti o n di ifarahan ibukun rẹ lọna ti o peye ninu aye rẹ lọwọ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ninu ààlọ́ ti Jesu pa lori ọkunrin kan ti o fun awọn iranṣẹ rẹ ni owo kan lati fi ṣiṣẹ, a ri ẹkọ atigbadegba kan ti o ṣe pataki dimu. Oun naa si ni pe ẹnikẹni ti ko ba ni fi ọpọlọ pipe ṣe amulo awọn ibaṣepọ, amuyẹ, anfaani tabi oore-ọfẹ ti Ọlọrun fun laye yi ko ni pọ si ni iṣẹ rere ati ni awọn nkan daradara ti aye yi. Kiki awọn ti o ba n lo ọpọlọ wọn lati fi gbogbo igba ṣe amulo awọn nkan ti Ọlọrun fun wọn ni yoo tẹsiwaju lati ma pọ si ni iṣẹ rere ati ni nkan daradara. 

Bi akọsilẹ naa ti ṣe lọ, ọkunran kan ti o n lọ si irin-ajo jinjin pinnu lọkan rẹ lati fun awọn ọmọ ọdọ rẹ kan ni diẹ lara owo rẹ, ki wọn ba le fi ṣiṣẹ. Eyi jasi pe ko fẹ ki owo rẹ kan joko kalẹ sinu kolo rẹ, ki eruku ma bo mọ ibẹ nigba ti ko ba si nile. Nitorina, o fun awọn iranṣẹ rẹ lara rẹ lati ṣiṣẹ, gẹgẹ bi ipa ẹnikọọkan wọn ti mọ. O fun ẹnikan ni talẹnti marun-un. O fun elomiran ni talẹnti meji. O si tun fun elomiran ẹwẹ ni talẹnti kan.

Wayi o, lẹyin ọjọ pipẹ, ọkunrin yi pade lati irin-ajo rẹ, o si bẹrẹ si ni ṣe agbeyẹwo nkan ti awọn ọmọ ẹyin rẹ ṣe pẹlu owo ti o fun wọn. Si iyalẹnu rẹ, meji pere lara wọn ni o ṣiṣẹ pẹlu owo ti o fun wọn, ti wọn si sọ di pupọ si. Ọkunrin ti o gba talẹnti marun-un jẹ ere talẹnti marun-un miran pẹlu owo ti a fun. Bẹẹ si ni pẹlu, ọkunrin ti o gba talẹnti meji naa jẹ ere talẹnti meji miran pẹlu owo ti a fun. Amọ awawi lasan ni ọkunrin ti a fun ni talẹnti kan mu wa. Ko ṣe nkankan pẹlu talẹnti ti a fun. Nitorina ko jẹ ere kankan pẹlu rẹ. 

Ki wa lo fa ti ọkunrin yi ko fi ṣe nkankan pẹlu talẹnti tirẹ? Idahun ti awọn eniyan ṣaba ma n fun ibere yi ni pe ọkunrin yi ko ṣe nkankan pẹlu talẹnti tirẹ nitoripe o woye pe o ti kere ju, ti a ba ṣe afiwe re pẹlu eyi ti a fun awọn yoku. Ṣugbọn eyi ko ki i ṣe idi ti ko fi lo rara. Lakọkọ, oluwa wa fun ẹnikọọkan wọn ni owo ti o fun un ni ibamu pẹlu ipa rẹ. Nitorina, nkan ti ipa iranṣẹ yi ka ni a fun. Ekeji, awọn olukọtan jẹ ki o ye wa pe talẹnti kan ni akoko yi dabi ki a ko owo iṣẹ ojumọ alagbese kan jọ fun bi ogun ọdun. Nitorina, ọpọlọpọ owo ni a fun ọkunrin yi.  

Eyi wa jẹ ki o ye wa pe ko ki i ṣe nitoripe owo ti a fun kere ni ko ṣe ṣe nkankan pẹlu rẹ. Dipo bẹẹ, gẹgẹ bi ọrọ oun funrarẹ, nitoripe ẹru lati padanu owo naa n ba a ni ko ṣe ṣe nkankan pẹlu rẹ (Matiu 25:25). Ṣugbọn bi oluwa rẹ ti ṣe sọ fun, ti o ba jẹ wipe o fi owo yi si ile ifowopamọsi ni, nṣe ni ko ba gba a pada pẹlu èlé lori rẹ. Nitorina, ẹ̀rù ko to gẹgẹ bi idi fun lati ma ṣe nkankan pẹlu aduru owo nla yi. O ni iṣoro miran, eyi si ni imẹlẹ. O tunmọ si pe nitoripe ọkunrin yi ya ọlẹ ninu ọpọlọ rẹ ati pẹlu ọwọ rẹ ni ko ṣe gbiyanju rara lati wo ọna ti o le gba sọ owo ti a fun di pupọ si. Nitori eyi, o wa papa jẹ ki nkan ti oluwa rẹ ko fẹ ki o ṣẹlẹ ṣẹlẹ — o jẹ ki owo rẹ kan wa ni ojukan laipọsi.

Ki a ma fa ọrọ gun, yatọ si ijiya ti a fun ọkunrin ọlẹ ati alailere yi, oluwa rẹ tun paṣẹ pe ki a gba owo ti a fun kuro lọwọ rẹ, ki a si fun ọkan lara awọn iransẹ ti wọn ti fi ara wọn han gẹgẹ bi ẹni ti o dangajia lati ri nkan gba si lọwọ ọga wọn. Ni ipari, Jesu Oluwa wa wa sọ wipe bi nkan ti ṣe ri gẹlẹ niyi ninu ijọba Ọlọrun. Awọn ti o ba kọbiara si nkan ti Ọlọrun fun wọn – eniyan, dukia, amuyẹ, ẹbun, ẹkọ, ipo ati bẹẹbẹẹ lọ – bi o ti wu ki awọn nkan yi kere tabi ki wọn ma ṣe pataki to – ti wọn si n ṣe amulo to peye wọn nikan naa ni yoo  tẹsiwaju lati maa gbe ga ati lati jẹ ki wọn ma pọ si ni nkan rere. Ṣugbọn awọn ti ko ṣe nkankan pẹlu nkan ti O fun wọn ko ni ireti mi ju pe ki a tun gba nkan ti a fun wọn kuro lọwọ wọn, bi o ti wu ki nkan naa kere to. Eyi si ni alaye fun bi awọn otoṣi eniyan ni ọpọ igba ṣe ma n toṣi si ati ti awọn olowo ati gbajumọ eniyan ni ọpọ igba ṣe ma n di olowo ati ilumọọka si. 

Nitorina, ti o ko ba ma ṣe amulo awọn nkan ti Ọlọrun fun ọ tabi tí Ó ti jẹ ki o ri gba nipa oore-ọfẹ rẹ, nṣe ni o n fi ara rẹ han bi alailere ati bi ẹni ti ibi giga ko tọ si laye yi. Iwọ gan an wa ni ọta ara rẹ lori ọrọ yi, bi awawi rẹ ṣe wu ko ri. Iwọ ni o n de ara rẹ lọna, ti o si tun n ja ara rẹ kulẹ. Nitorina, ma ṣe reti ki nkan dara si fun ọ nigba ti o jẹ pe yoo buru si ni.

Wayi o, adura mi ni pe ki nkan ma fi gbogbo igba dara siwaju ati siwaju fun ọ dipo ko ma buru si. Ṣugbọn gbigbadura nipa rẹ nikan ko to. Iwọ na nilo lati ji kuro ninu oorun rẹ, ki o ye wa awawi fun ikuna tabi ìṣẹ́ rẹ mọ, ki O si ṣe ìdámọ̀ ati àmúlò ohun gbogbo ti Ọlọrun fun ọ ti o le lo lati pọ si ni iwulo, iṣẹ rere ati dukia ni aye yi. Bi o ba si ṣe n ṣe eyi, iyalẹnu ni yoo jẹ fun ọ nigba ti o ba ri bi awọn iIbukun Ọlọrun ti o ti farasin ninu aye ṣe bẹrẹ si ni farahan ni ẹkunrẹrẹ.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ọ̀tá ara rẹ | Pst. J.O. Lawal | Òkúdù 26, 2022 | Vol. 11, No. 8 Read More »

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ TẸSALÓNÍKÀ KÍNNÍ. | AYỌKA: 1TẸSALÓNÍKÀ 2:13-16 | ỌJỌ́RÚ 08, ÒKÚDÙ 2022

ÀKỌ́SÓRÍ: “”Nitori ẹyin tikarayin mọ, ara, pe ibẹwo wa si yin kii ṣe lasan.” (1Tẹsalonika 2:1)

Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ

Ninu ẹkọ ti a kọ pari ninu lẹta Pọọlu kinni si ijọ Ọlọrun ti o wa ni Tẹsalonika, a ri irufẹ iṣẹ iranṣẹ ti o le mu ifẹ Ọlọrun wa si imuṣẹ laarin alaigbagbọ ati laarin awọn ti o gbagbọ pẹlu. Eyi si jẹ iṣẹ iranṣẹ ti afojusun rẹ duro lori bi yoo ṣe gba oriyin Ọlọrun dipo oriyin eniyan ati eyi ti ko ki i wo bi nkan ba ti ṣe rọrun si ki o to fi ara rẹ jin fun ifẹ Ọlọrun. Amọ ṣa o, pe iṣẹ iranṣẹ ojiṣẹ Ọlọrun kan munadoko ko wa tunmọ si pe o di dandan ki o so eso rere ninu aye awọn ti o ba tọ wa tabi ti o n waasu si. Iha ti awọn ti a mu ọrọ Ọlọrun tọ wa ba kọ si ọrọ ti a mu tọ wọn wa naa ni ipa pataki lati ko lori irufẹ eso ti aye wọn yoo so. 

Fun apẹẹrẹ, bi o tilẹ jẹ wipe iṣẹ iranṣẹ Mose munadoko, ti o si jẹ eyi ti Ọlọrun funrarẹ tẹwọgba, ko so eso rere ninu aye ọpọ awọn ọmọ Isiraẹli ti o ko jade lati ilẹ Ijibiti. Gẹgẹ bi a ti fi ye wa ninu bibeli, ọpọlọpọ wọn ni ko wọ ilẹ ileri ti a mu wọn jade lati wọ. Ki si ni idi? Idi ni pe wọn ko kọ iha ti o tọ si iṣẹ iranṣẹ Mose ati awọn ọrọ Ọlọrun ti o mu tọ wọn wa. Nitorina, ọtọ ni ki ojiṣẹ Ọlọrun ja fafa, ki o si mu iṣẹ ti Ọlọrun gbe fun ni pataki ati pẹlu ọkan ti o pe; ọtọ si tun ni ki awọn ti a ran si naa mu ọrọ Ọlọrun ti o mu tọ wọn wa ni pataki, ki wọn si gba pẹlu ọkan ti o pe. Aijẹbẹ, ete Ọlọrun ko ni wa si imuṣẹ lori aye wọn. 

Wayi o, a n sọ eleyi kí á ma bà rò wípé òjíṣẹ́ Ọlọrun naa ni a gbọdọ da ẹbi le lori ti awọn ọmọ ijọ rẹ ko ba dagba soke ninu ẹmi tabi ki wọn ma rin ni pipe niwaju Ọlọrun, bi o ti ṣe tọ ati yẹ. Ọpọ ninu ijọ ni ko dagba soke bi o ti ṣe tọ loni nitoripe awọn funra wọn ko kọ iha ti o tọ si iṣẹ iranṣẹ awọn ti a ran si wọn. Ọpọ ni o si wa ni ipo aigbagbọ loni pẹlu, ti Eṣu ati awọn ọmọ ogun rẹ n pọn loju nitoripe wọn kọ lati ṣe amulo oore-ọfẹ Ọlọrun ti a n mu tọ wọn wa lojoojumọ tabi loorekoore.

Ranti pe Jesu Oluwa wa sọ wipe, “Ẹni ti o ba gba wolii ni orukọ wolii, yoo jẹ ere wolii; ẹni ti o ba si gba olododo ni orukọ olododo yoo jẹ ere olododo.” (Matiu 10:41) O si sọ eyi nitoripe ọpọ awọn eniyan rẹ, iyẹn awọn Juu ti O ni anfaani lati jẹ igbadun iṣẹ iranṣẹ rẹ ni ko jẹ igbadun rẹ. Ki si ni idi? Idi ni wipe wọn ko gbaagbọ tabi gba ọrọ Ọlọrun ti O mu tọ wọn wa gbọ. Nitorina, ọrọ rẹ ko so eso ti Ọlọrun fẹ ki o so ninu aye wọn. Ti iṣẹ iranṣẹ Jesu ba wa kuna lati so eso rere ninu aye ọpọ ti o ni oore-ọfẹ lati gbọ ọrọ rẹ, o yẹ ki a mọ pe ko si ara kankan ti iranṣẹ rẹ kankan le da ti awọn ti a ran si ba kuna lati gba ọrọ rẹ gbọ, ki wọn si ṣiṣẹ ni ibamu pẹlu rẹ. (Wo: Johanu 1:10-13; Johanu 15:18-25)

ÌHÀ TÍ Ó TỌ́ SÍ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Nkan ti a n sọ nipe ko si bi iṣẹ iranṣẹ awọn ojiṣẹ Ọlọrun ti o n tọ wa wa ṣe le munadoko to, ti a ko ba tẹwọgba wọn ati ọrọ Ọlọrun ti wọn n mu tọ wa wa bi o ti ṣe tọ ati bi o ti ṣe yẹ, iṣẹ iranṣẹ wọn ko ni so eso rere ninu aye wa. Gẹgẹ bi Pọọlu ti sọ siwaju ninu lẹta yi, iṣẹ iranṣẹ rẹ so eso rere ninu aye awọn ara Tẹsalonika to bẹẹ gẹẹ ti iroyin igbagbọ wọn ṣe n tan kalẹ kaakiri gbogbo ilu ati awọn agbegbe ti o yi wọn ka. Ki lo si fa? Iha ti wọn kọ si iṣẹ iranṣẹ apọsiteli yi ati awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ ni o fa. Iwọ naa wo nkan ti Pọọlu sọ lori eyi:

“Nitori eyi ni awa ṣe n dupẹ lọwọ Ọlọrun pẹlu ni aisinmi. Pe nigba ti ẹyin gba ọrọ ti ẹyin gbọ lọdọ wa, ani ọrọ Ọlọrun, ẹyin ko gba a bi ẹni pe ọrọ eniyan. Ṣugbọn ẹ gba a gẹgẹ bi o ti jẹ nitootọ, bi ọrọ Ọlọrun, eyi ti o ṣiṣẹ gidigidi ninu ẹyin ti o gbagbọ pẹlu.” (1Tẹsalonika 2:13)

Njẹ o ri bayi? Awọn ara Tẹsalonika yi ko ri ọrọ Ọlọrun ti a mu tọ wọn gba gẹgẹ bi ahesọ ṣugbọn wọn ri gẹgẹ bi otitọ ọrọ Ọlọrun. Lotitọ, ko ki i ṣe bi ẹnu oniwaasu ba ṣe dun si tabi bi o ba ṣe mọ ọrọ gbe kalẹ si ni yoo ṣokunfa igbagbọ awọn ti o ba gbọ ọrọ rẹ. Iṣẹ Ẹmi mimọ ni lati jẹ ki awọn eniyan ri ọrọ Ọlọrun gẹgẹ bi otitọ ninu ọkan wọn, ki wọn si gbe igbesẹ ti o tọ lori rẹ (Johanu 16:8-11; 1Kọrinnti 12:3). Amọ ẹni ti o ba ni lọkan lati ṣe ifẹ Ọlọrun tẹlẹ ni yoo kọbiara si oye ti Ẹmi Ọlọrun fẹ fi ye lori otitọ ọrọ rẹ (Jọhanu 7:17). Ẹni ti ko ba fẹ ṣe ifẹ Ọlọrun ko ni kọbiara si ọrọ rẹ, bi o tilẹ mọ ninu ọkan rẹ pe otitọ ni.

Awọn ara Tẹsalonika, ti wọn ti fi igba kan ri jẹ abọriṣa gba ọrọ Ọlọrun ti Pọọlu mu tọ wọn wa gẹgẹ bi otitọ. Eyi si fi ye wa pe awọn ti o gbagbọ yi ti ni lọkan lati mọ otitọ ati lati ṣiṣe le lori ki wọn to ṣe alabapade iṣẹ iranṣẹ Pọọlu. Niwọn igba ti wọn si ti gbagbọ, ọrọ Ọlọrun ti wọn gbọ bẹrẹ si ni ṣisẹ ninu aye wọn, o si bẹrẹ si ni so eso ti Ọlọrun fẹ ko so nibẹ, to bẹẹ gẹ ti Pọọlu ṣe tẹsiwaju lati sọ nipa wọn pe, “Nitori, ara, ẹyin ṣe afarawe awọn ijọ Ọlọrun ti n bẹ ni Judia, ninu Kirisiti Jesu. Idi ni pe ẹyin pẹlu jiya ju wọn lọ lọwọ awọn ara ilu yin, gẹgẹ bi awọn pẹlu ti jiya lọwọ awọn Juu.” (1Tẹsalonika 2:14)

Nibakanna, ti awa naa ba fẹ ṣe ifẹ Ọlọrun, ti a ba ni lọkan lati pilẹ aye wa ati ohun gbogbo ti a n ṣe lori otitọ, o di dandan ki a gba ọrọ otitọ rẹ gbọ nigba yowu ti o ba tọ wa wa. Ti a ba si gba ọrọ otitọ rẹ gbọ, o di dandan ki o ṣiṣẹ ninu aye wa, ki o si so eso ti Ọlọrun fẹ ki o so. Ti a ba wa woye pe aye wa ko so eso ti Ọlọrun fẹ ki o so tabi pe ko lọ ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ, nṣe ni o yẹ ki a kọkọ wo iha ti a kọ si ọrọ rẹ dipo ti a o fi ma da awọn ojiṣẹ rẹ ti a ran si wa lẹbi. 

Ọpọ ni o n lọ lati inu ijọ kan de inu ijọ miran loni, bi ọpọ miran si tun ṣe n lọ lati ori oke kan de ori oke miran. Ki lo si fa? Wọn ko ni igbagbọ to ninu iṣẹ iranṣẹ awọn alufa tabi adari ijọ wọn. Amọ bi mo ti ṣe sọ siwaju, ko ki i ṣe gbogbo igba naa ni o jẹ wipe iṣẹ iransẹ awọn ti a ran si wa ti ko munadoko to ni ko jẹ ki aye wa dagba soke tabi lọ siwaju bi o ti ṣe tọ ati bi o ti ṣe yẹ. Niwọn igba ti a ko ba ti kọ iha ti o tọ si iṣẹ iranṣẹ wọn, ko si ni bi aye wa yoo ṣe jere iṣẹ iranṣẹ naa.

ỌRỌ IPARI

Ọrọ Ọlọrun lagbara lati ṣiṣẹ ninu aye wa fun imuṣẹ ifẹ rẹ. Amọ ti a ko ba kọ iha ti o tọ si, ki a si gba ọrọ rẹ bi ọrọ rẹ dipo bi ọrọ eniyan, ko ni so eso rere ninu aye wa, bi o ti wu ki awọn ti o n bọ wa pẹlu ọrọ rẹ munadoko to.

IBEERE

–    Ki ni o ro pe o fa ti ọpọ ko ki fi gba ọrọ Ọlọrun gẹgẹ bi ọrọ rẹ ninu ijọ loni?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2022,  Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ TẸSALÓNÍKÀ KÍNNÍ. | AYỌKA: 1TẸSALÓNÍKÀ 2:13-16 | ỌJỌ́RÚ 08, ÒKÚDÙ 2022 Read More »

Tan ìhìnrere náà kálẹ̀. | Pst. J.O. Lawal. | Òkúdù 19, 2022. | Vol. 11, No. 7

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lọpọlọpọ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu yi. Mo gbadura pe ki a ka ọ yẹ fun ipe Ọlọrun ti o ti ri gba ninu ọsẹ naa ati ni gbogbo iyoku ọjọ aye rẹ. Amin.

Ọkan lara awọn nkan ti Oluwa n reti ki ẹnikọọkan ti o ti jẹ ajogun didara ati igbala rẹ ma ṣe ni titan ihinrere awọn nkan ti O ti ṣe fun wọn de ọdọ awọn miran. Nipa ṣiṣe eyi, awọn ti wọn ba tan ihin naa de ọdọ wọn yoo le ni iwuri lati wa sọdọ rẹ lati ni iriri didara rẹ ninu aye ti awọn naa. Fun apẹẹrẹ, lẹyin igba ti O ti tu ọkunrin were ti awọn legioni ẹmi eṣu n gbe inu rẹ silẹ tan, Oluwa sọ fun pe, “Lọ si ile rẹ ki o si sọ fun awọn ara ile rẹ, bi Oluwa ti ṣe ohun nla fun ọ, ati bi o si ti ṣaanu fun ọ.” (Maaku 5:19)

Njẹ ọkunrin yi wa ṣe bi Oluwa ti paṣẹ fun bi tabi ko ṣe bẹẹ? O ṣe bẹẹ! Ka tilẹ sọ otitọ, o ṣe ju bi a ti lero pe yoo ṣe lọ. Ko ki i ṣe awọn ara ile rẹ nikan ni o sọ nkan ti Ọlọrun ṣe fun fun. Nṣe ni o tun lọ kaakiri lati ma sọ fun gbogbo awọn ti o bikita lati gbọ tirẹ ni agbegbe kan ti a n pe ni ‘Dekapoli, eyi ti o tunmọ si ‘Ilu Mẹwa’.

Iwọ naa gbe yẹwo. Ọkunrin yi lọ kaakiri agbegbe ilu mẹwa tan, o si n sọrọ nipa nkan ti Jesu ṣe fun nibẹ. Ki ni idi? Akọkọ, idi ni pe o mọ nkan ti Oluwa ṣe fun loore gidigidi. Ekeji, idi ni pe o fẹ ki awọn miran ti wọn wa labẹ ide Satani naa mọ pe wọn le gba idande nipa titọ Oluwa wa, bi o ti wu ki ọrọ wọn buru to.

Nibakana, ti Oluwa ba ti dara si wa nitootọ ninu ijọ wa, ojuṣe wa si ni lati jẹ ki awọn miran mọ nipa rẹ. Ti o ba jẹ pe nitootọ ni O n yi aye wa pada si rere, ti O si n mu ki a ni itẹsiwaju nipasẹ ọrọ rẹ, o wa yẹ ki a jẹ ki awọn ọrẹ, ẹbi, akẹgbẹ wa ni ibi iṣẹ tabi ni ile-ẹkọ ati aladugbo mọ pe awọn naa le jẹ alajọpin didara rẹ pẹlu wa. Bi mo si ti ṣe sọ siwaju, Ọlọrun funrarẹ n reti pe ki a ṣe eyi. Idi si ni pe ọkan pataki lara awọn idi ti O fi n ṣe rere fun wa ni ki a ba le jẹ ilẹkun fun lati le wọnu aye awọn ti o wa ni ayika wa, ki O si ṣe rere fun awọn naa pẹlu.

Nkan ti eyi wa tunmọ si ni pe ti a ba kọ lati tan ihinrere didara rẹ si wa de ọdọ awọn ti o wa ni ayika wa, ko ki i ṣe pe a n fi ara wa han gẹgẹ bi alanikanjọpọn nikan, nṣe ni a tun n di iṣẹ rẹ lọwọ. Ko si wa si bi a o ṣe ma fi anikanjọpọn di iṣẹ Ọlọrun lọwọ ti a ko si ni jẹ iya rẹ, okere ni o tabi o pọ. Boya eyi gan tilẹ ni idi ti awa kan fi n ni iriri ainitẹsiwaju ninu aye wa. Yoo wa bojumu ti a ba tete ronupiwada, ki a si bẹrẹ si ni fi itara dari awọn ti o wa ni ayika wa lati ni iriri didara Ọlọrun ti a n jẹ igbadun rẹ lọwọlọwọ. 

Wayi o, eyi ko wa jasi pe ki a fi túláàsì tabi àrékérekè mu ẹnikẹni lati di alabapin pẹlu wa ninu igbadun didara Ọlọrun. Dipo bẹẹ, o tunmọ si pe ki a ṣe ohun gbogbo ti o wa ni ikawọ wa lati fun iye awọn yowu ti a ba ni oore-ọfẹ lati fun ni iwuri lati wa sọdọ Oluwa funra wọn, ki wọn ba le ri bi O ti ṣe le dara si wọn ati ṣe wọn ni aanu to. Ki Ẹmi Ọlọrun si ma fi gbogbo igba kọ ọkan wa ati fun un ni okun lati mu ọrọ yi ni pataki ninu aye wa, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Tan ìhìnrere náà kálẹ̀. | Pst. J.O. Lawal. | Òkúdù 19, 2022. | Vol. 11, No. 7 Read More »

Fi ara rẹ si ipo irẹlẹ. | Pst. J.O. Lawal. | Òkúdù 12, 2022. | Vol. 11, No. 6

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lailodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Òkúdù 2022. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun jẹ ki ọkan rẹ wa ni itẹriba niwaju rẹ ni gbogbo igba, ki ainitẹsiwaju ma ba gba ijọba aye rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Gẹgẹ bi a ti sọ fun wa ninu bibeli, idi ti angẹli Ọlọrun ti a n pe ni Satani loni fi di ẹni ti a n pe ni Satani ni igberaga. Ni ibẹrẹ-pẹpẹ, Ọlọrun da ni pipe ninu ẹwa ati ninu ọgbọn, a si tun fi si ipo nla laarin awọn angẹli Ọlọrun yoku. Ṣugbọn nigba ti o jẹ ki ẹwa rẹ ko si lori, Ọlọrun re jabọ kuro ni ipo atata ati ipo agbara ti o wa. (Isikiẹli 28:11-19)

Ki wa ni idi ti a fi sọ eyi fun wa ninu bibeli? Oun naa ni ki a le mọ pe Ọlọrun korira igberaga. Ki lo si fa ti O fi korira igberaga? Idi ni pe igberega jẹ ami wipe a ko fẹ gbe oriyin ti o jẹ tirẹ fun lori awọn nkan daradara ti a ni tabi ti a n gbe ṣe. Bi a si ti ri ninu bibeli, gbogbo wa ko jẹ nkankan lalaisi Ọlọrun ati pe a ko le da ohunkohun ni lailisi rẹ. Oun ni ẹlẹda wa ati ẹlẹda ohun gbogbo ti o n bẹ. Nitorina, ko si nkan ti a le sogo le lori ninu aye yi tabi ninu aye eyi ti o n bọ. Òun ti wà ki ohun gbogbo to wa ati pe ohun gbogbo wa lati ọdọ rẹ, wọn si tun jẹ tirẹ. (Wo: Saamu 24:1; Kolose 1:16:17; Ifihan 4:11)

Ṣugbọn nigba ti a ba kọ lati gba ododo yi, ti a si bẹrẹ si ni ṣe bi pe a ja mọ nkan, boya si Ọlọrun tabi si awọn eniyan, nṣe ni a n gbe ara wa gori ẹṣin aáyán, ti a si n fi ara wa si ipo ti Ọlọrun yoo fi re wa jabọ, gẹgẹ bi O ti ṣe re Satani jabọ. Bibeli sọ wipe, “Ọlọrun n kọ oju ija si awọn agberega; ṣugbọn O n fi oore-ọfẹ fun awọn onirẹlẹ.” Nitorina, iru ẹni yowu ti a jẹ tabi ipo yowu ti a wa ni aye yi, ni kete ti a ba ti fi aye gba igberaga ninu aye wa, ni kete ti a ba ti bẹrẹ si ni ronu tabi wiwu bi igba ti o jẹ pe Ọlọrun ni wa naa ni a o ti ri pe O ti n doju ija kọ wa. Ti a ba si wa kọ lati ronupiwada ni kiakia, ko ni pẹ rara ti a o fi ri pe a ti di ẹni itẹmọlẹ tabi pe a ti di ero ọrun apadi. (Wo: Jemisi 4:6; 1Peteru 5:5)

Nitorina, ma ṣe fi aye silẹ fun irufẹ igberaga kankan ninu aye rẹ, bi o ti wu ki aye ma lọ ni mẹlọmẹlọ fun ọ to tabi bi ipo atata ti o wa ti le ga to tabi bi o ti wu ki o wulo ni ọwọ Ọlọrun to. Ranti pe Satani naa ti fi igba kan ri jẹ ohun elo iyin ti o ga ni ọwọ Ọlọrun. Ṣugbọn igberaga ba aye rẹ jẹ. O ṣi le ba aye awa naa jẹ pẹlu. O le fi idibajẹ sinu ẹwa, ọgbọn, imọ, ipo ati iwulo wa, ti awa naa ba fi aye gba. O le sọ wa di eranko buburu, ẹranko buburu ti Ọlọrun ko ni fẹ ba ni ohunkohun ṣe pẹlu.

Ṣe nkan ti o wa fẹ ni eyi? Ṣe o wa fẹ di ẹni ti Ọlọrun yoo ma lepa lati gbe ju sọnu tabi palẹ rẹ mọ? Mo mọ pe o ko fẹ ki nkan ri bẹ fun ọ. Ṣugbọn nkan le papa ri bẹ fun ọ, ti o ba fi aye gba irufẹ igberaga kan tabi omiran ninu aye rẹ, Nitori eyi, ṣọ ara rẹ. Kiyesi bi o ti ṣe n ba Ọlọrun ati awọn eniyan lopọ. Njẹ ki Ẹmi Ọlọrun ṣi oju rẹ si irufẹ igberaga yowu ti o le wa ninu rẹ, ki o ba le ṣe ohun ti o tọ nipa rẹ ki o to yọri si iṣubu rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Fi ara rẹ si ipo irẹlẹ. | Pst. J.O. Lawal. | Òkúdù 12, 2022. | Vol. 11, No. 6 Read More »

Ṣiṣẹ́ kárakára si fun un. | Pst. J.O. Lawal. | Òkúdù 05, 2022. | Vol. 11, No. 5

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu oṣu Òkúdù 2022. Mo si gbadura pe ki ọkan rẹ ma fi gbogbo igba gba okun ati iwuri lati ma pọ si ninu iṣẹ Oluwa dipo ki o ma rẹwẹsi ninu rẹ ni gbogbo oṣu yi ati titi Oluwa wa yoo fi de. Amin. 

Pọọlu, ninu lẹta rẹ kan si awọn ara Kọrinnti, sọ wipe, “Ṣugbọn nipa oore-ọfẹ Ọlọrun, ni mo ṣe ri bi mo ti ri: oore-ọfẹ rẹ ti a fi fun mi ko si jẹ asan; ṣugbọn mo ṣiṣẹ lọpọlọpọ ju gbogbo wọn lọ: ṣugbọn ki i ṣe emi, bi ko ṣe oore-ọfẹ Ọlọrun ti o wa pẹlu mi.” (1Kọrinnti 15:10) Bawo ni o ṣe ṣeeṣe fun Pọọlu lati ṣiṣẹ karakara fun Oluwa ju awọn apọsiteli rẹ yoku lọ? Nipasẹ oore-ọfẹ Ọlọrun ni. Nitorina, ko ki i ṣe nitori pe o ja fafa ju wọn lọ, ni imọ ju wọn lọ tabi ṣe olododo ju wọn lọ ni o se ṣiṣẹ karakara ju wọn lọ; dipo eyi, nitori pe o ṣe amulo ti o peye gbogbo nkan ti Ọlọrun pese fun lati sin in ni o ṣe ṣiṣẹ karakara ju wọn lọ. 

Ṣe Pọọlu lotitọ wa ṣiṣẹ karakara ju gbogbo awọn apọsiteli Oluwa yoku lọ? Ni lilo oṣuwọn ti ara rẹ, o gbagbọ pe oun ṣiṣẹ julọ wọn lọ. Boya o wa jana tabi ko jana lori ọrọ yi jẹ nkan ti a o ma mọ nigba ti Oluwa wa ba de lati pin ere fun gbogbo awọn eniyan mimọ rẹ. Ṣugbọn, eyi ko ki i ṣe nkan ti o yẹ ki a ma ṣe àríyànjiyàn le lori. Nkan ti o ṣe pataki si wa lati kọbiara si lori ọrọ yi ni pe ọkunrin yi ko jẹ ki oore-ọfẹ Ọlọrun ti a tu le lori lẹkunrẹrẹ ṣofo. Dipo ki o fi ṣofo, nṣe ni o lo lati sin in tọkantọkan, lati sin lọpọlọpọ si titi ti akoko rẹ ni aye yi fi wa si opin. 

Amọ ṣe awa naa le sọ nkankanna nipa ara wa? Ṣe a le sọ pe awa naa n ṣe amulo oore-ọfẹ Ọlọrun lati pọ si ninu iṣẹ irẹ? Pọọlu, ninu lẹta kanna si awọn ara Kọrinnti, sọ fun wọn pe, “Nitori naa ẹyin ara mi olufẹ, ẹ maa duro ṣinṣin, laiyẹsẹ, ki ẹ si maa tẹsiwaju ninu ṣiṣe iṣẹ Oluwa nigba gbogbo, niwọn bi ẹyin ti mọ pe iṣẹ yin kii ṣe asan ninu Oluwa.” (1Kọrinnti 15:58) Ṣe o ri bayi? A gba awọn ara yi niyanju lati ma ya ọ̀lẹ nidi iṣẹ Ọlọrun ṣugbọn lati ma fi ara wọn jin fun ni gbogbo igba.

Ki si ni idi? Idi ni pe laalaa wọn ko ni lọ lasan. Eyi tunmọ si pe Ọlọrun yoo pin wọn ni ere fun ohunkohun ti wọn ba ṣe fun. Iwọ naa wa ro wo. Bi o tilẹ jẹ wipe Oluwa ni O n pese ohun gbogbo ti a nilo lati sin in, sibẹsibẹ O ṣe ileri lati pin wa ni ere fun ohunkohun ti a ba ṣe fun un. Bi o si tun tilẹ jẹ wipe gbogbo ogo aṣeyọri wa ni ṣiṣẹ sin jẹ tirẹ nikan, sibẹsibẹ O ṣe ileri lati pin wa ni ere fun laalaa yowu ti a ba ṣe fun.

Idi wa niyi ti a ṣe nilo lati jígìrì, ti o ba jẹ wipe a ti n ṣun, ki a si mura si iṣẹ rẹ. Bẹẹni, a nilo lati dẹkun lati ma fi ara pamọ tabi sa fun iṣẹ rẹ tabi lati ma wa awawi fun bi a ṣe n rẹwẹsi ni ṣiṣe iṣẹ rẹ dipo ki a ma pọ si ni ṣiṣe e. A si tun nilo lati dẹkun lati ma fi oju alaṣeju tabi alaṣehan wo awọn ti o ba mura si iṣẹ rẹ layika wa. Idi si ni pe ko tọ si wa lati ṣe idajọ bi iṣẹ ẹnikẹni fun Ọlọrun ṣe munadoko si. Iṣẹ Ọlọrun pọ́nbélé ni eyi jẹ.

Iṣẹ tiwa, ẹwẹ, ni ki a ṣe bi Pọọlu ti ṣe, ki a si ma woye bi a ṣe le ṣe amulo oore-ọfẹ Ọlọrun ni ojumọ kọọkan lati ṣiṣẹ karakara si fun ju ti atẹyin wa lọ ati ju awọn ti o wa ni ayika wa lọ? Ki si ni idi? Ṣe ki a ba le ma fọ́nu lori iṣẹ wa ni? Rara O! Dipo bẹẹ, idi ni pe eyi yoo jẹ ki a le ru awọn ọmọ Ọlọrun ti o wa ni ayika wa soke lati ma fi ara wọn jin siwaju ati siwaju si lati fun ni iṣẹ-sin ti o tọ, ti o si munadoko. Adura mi si ni pe ki ọkan rẹ ma fi gbogbo igba gbinájẹ lati ṣe eyi, ni orukọ Jesu. Amin. 

Kí o ní oṣù Òkúdù alárinrin

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ṣiṣẹ́ kárakára si fun un. | Pst. J.O. Lawal. | Òkúdù 05, 2022. | Vol. 11, No. 5 Read More »

ÀKỌ́RÍ: ẸKỌ NINU IWE TẸSALONIKA KINNI

(AYỌKA: 1TẸSALONIKA 1:1-10)

ÀKỌ́SÓRÍ: “”Nitori ẹyin tikarayin mọ, ara, pe ibẹwo wa si yin kii ṣe lasan.” (1Tẹsalonika 2:1)

Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ Gẹgẹ bi a ti ri ninu iwe Iṣe awọn Apọsiteli, ilu Tẹsalonika jẹ ọkan lara awọn ilu ti Pọọlu ati awọn alabaṣiṣẹ rẹ ninu ipolongo ihinrere Jesu ti waasu nigba ti o jade ni igba keji fun irinajo iṣẹ iranṣẹ rẹ gẹgẹ bi apọsiteli ati olukọ ọrọ Ọlọrun. Akoko diẹ perete ni wọn si ni lati waasu ni ilu yi. Idi si ni pe awọn Juu ti o wa nibẹ ko fi wọn lara balẹ rara. Nṣe ni wọn ṣe inunibini wọn to bẹẹ gẹẹ ti wọn fi nilo lati sa kuro ni ilu yi ni ọganjọ-oru. Wọn ko si tun fi wọn lọrun silẹ titi wọn fi ri wipe Pọọlu tun fi Beria, ilu miran ti wọn lọ nigba ti wọn kuro ni Tẹsalonika, silẹ fun wọn. Wọn si ṣe gbogbo eyi nitoripe wọn ko fẹ ki ihinrere Jesu Kirisiti tan kalẹ ni ibi gbogbo, ki o si sọ awọn ti o ba gbaagbọ di alabukunfun. (Wo: Iṣe Apọsiteli 17:1-15)

Amọ ṣa o, niwọn igba ti o jẹ wipe Pọọlu ati awọn arakunrẹ ninu iṣẹ-iranṣẹ ti ri oore-ọfẹ gba lọwọ Ọlọrun lati fun irugbin ọrọ rẹ sinu aye awọn kan ni Tẹsalonika, ko si inunibini kankan ti o le di irugbin yi lọwọ lati so eso rere. Lotitọ, Pọọlu gbiyanju, gẹgẹ bi a o ti ri ninu lẹta rẹ akọkọ si wọn, eyi ti a fẹ bẹrẹ si ni gbe yẹwo ninu ẹkọ yi, lati pada yọju si awọn ara yi. Ṣugbọn Sàtánì ko jẹ ki o ṣeeṣe fun. Idi si ni yi ti o fi wa pinu lati ran Timoti si wọn, ki o ba le bẹ wọn wo, ki o si mu iroyin wa nipa wọn. Nigba ti apọsiteli yi ati awọn yoku rẹ si wa pada bẹrẹ si ni gburo igbagbọ wọn, wọn ko le pa ayọ wọn mọ rara. Eyi lo si fa ti wọn ṣe kọ lẹta ti a fẹ gbe yẹwo yi si wọn lati gba wọn niyanju siwaju si ninu irinajo igbagbọ wọn.

`IJỌ ÀWÒKỌ́ṢE Wayi o, nkan akọkọ ti a ri ninu lẹta ni yi pe Pọọlu jẹ ki o ye wa ibi ti lẹta naa ti ṣe jade wa ati awọn ti a kọ ọ si nipa sisọ eyi: “Eyi ni iwe Pọọlu, Silifanu ati Timoti, ti a ko si ijọ awọn ara Tẹsalonika, ninu Ọlọrun Baba, ati ninu Jesu Kirisiti Oluwa: Ki Oore-ọfẹ ati alaafia Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ki o wa pẹlu yin.” (1Tẹsalonika 1:1) Bawo ni a ṣe ṣe apejuwe awọn onigbagbọ yi? A pe wọn ni olugbe ninu Ọlọrun Baba ati Jesu Kirisiti Oluwa. Eyi tunmọ si pe ibugbe nipa ti ara nikan ni Tẹsalonika jẹ fun awọn ara yi. Wọn tun ni ibugbe miran nipa ti ẹmi, eyi si wa ninu Ọlọrun ati ninu Ọmọ rẹ Jesu Kirisiti Oluwa wa. Bẹẹ gẹgẹ ni o si ri fun gbogbo ọmọ Ọlọrun patapata. Ibi yowu ti a le wa ninu aye yi, ibugbe ti ara ni. Ṣugbọn a ni ibugbe miran ninu Jesu Kirisiti funrarẹ nipa ti ẹmi. Eyi si ni o fi wa si ipo lati lo aṣẹ ati agbara rẹ lati gbe igbe aye ti o tẹ ẹ lọrun, ti o si tun nitunmọ ni ibi yowu ti a ba wa.

Nkan ekeji ti Pọọlu mẹnuba ninu lẹta yi ni i ṣe pẹlu nkan ti wọn n ranti awọn ara Tẹsalonika yi fun, eyi ti o si jẹ ki wọn ma dupẹ lọwọ Ọlọrun lori wọn. Iwọ naa wo nkan ti o sọ nipa wọn: “Awa n dupẹ lọwọ Ọlọrun nigba gbogbo nitori gbogbo yin, awa si n ranti yin ninu adura wa; Ni aisinmi ni awa n ranti iṣẹ igbagbọ, laalaa, ifẹ, suuru ati ireti yin ninu Oluwa wa Jesu Kirisiti, niwaju Ọlọrun ati Baba wa. Awa si mọ pe Ọlọrun ni o yan yin, ara olufẹ.” (1Tẹsalonika 1:1-4) Kini Pọọlu ati awọn yoku rẹ n ranti nipa awọn ara Tẹsalonika ninu Kirisiti? Wọn n ranti iṣẹ igbagbọ wọn. Eyi tunmọ si pe igbagbọ wọn ko ki i ṣe ti ẹnu lasan – wọn n ṣiṣẹ tọ ọ lẹyin. Wọn tun n ranti laalaa ifẹ wọn ati suuru ti ireti ti wọn ni fun bibọ Jesu bi sinu aye wọn. Eyi lo si fa ti wọn ṣe n fi gbogbo igba ranti wọn ninu adura, ti wọn si n ṣọpẹ niwaju Ọlọrun lori aye wọn, nitori pe wọn mọ daju pe ọmọ Ọlọrun tootọ ni awọn wọnyi jẹ.

Njẹ awọn ara wa ninu Oluwa naa le fọwọ sọya pe ọmọ Ọlọrun ni a jẹ nitooto? Ki tilẹ ni wọn a ma ranti nipa wa nigba ti a ko ba si pẹlu wọn tabi wa nitosi? Njẹ wọn n ranti wa gẹgẹ bi onigbagbọ ododo, olufẹ Ọlọrun ati eniyan ati ẹni ti o n mura silẹ de bibọ Jesu bi? Abi nṣe ni wọn n ranti wa gẹgẹ bi onijagidijagan, ọbayejẹ, alaigbọran, gbeborun, alagbere ati bẹẹbẹẹ lọ? Eyi ni yoo sọ irufẹ adura ti wọn yoo ma gba fun wa ati pe boya wọn yoo ma fi ọpẹ fun Ọlọrun lori aye wa tabi bẹẹkọ.

Lotitọ, bi apọsiteli yi tun ṣe fi ye wa ninu lẹta yi, irufẹ ọrọ ihinrere Jesu ti awọn eniyan naa ba gbọ tabi ba n gbọ ni ipa pataki lati ko lori irufẹ igbagbọ ti wọn yoo ni ati bi yoo ti ṣe fi ẹṣẹ mulẹ to. Ni tiwọn, ihinrere ti wọn mu tọ awọn ara Tẹsalonika yi wa jẹ eyi ti o jade pẹlu Ẹmi Ọlọrun funrarẹ ati agbara rẹ ati pẹlu idaniloju ti o peye lati ọdọ awọn naa ti wọn n waasu. Eyi n jẹ ki o ye wa pe ọrọ ihinrere ti yoo so eso rere ninu aye awọn eniyan gbọdọ jẹ eyi ti Ẹmi Mimọ tẹle ati eyi ti ẹni ti o n waasu naa ni idaniloju nipa iṣẹ ti o le ṣe ninu aye awọn ti o ba gbagbọ. Nitorina, ti ko ba da wa loju pe ihinrere Jesu ni agbara lati gbala ati lati mu ifẹ Ọlọrun wa si imuṣẹ ninu aye awọn eniyan, a ko lẹtọ lati ma polongo rẹ. Nkan ti ko si ni jẹ ki o da wa loju naa ni wipe ko i ti ṣiṣẹ ninu aye awa tikalara wa. (Wo: 1Tẹsalonika 1:5)

Nkan ẹkẹta ti Pọọlu mẹnuba ninu lẹta nipa awọn ara Tẹsalonika wọnyi da lori ọna ti igbagbọ wọn n gba ran awọn onigbagbọ ti o wa ni ibomiran lọwọ. Iwọ naa wo awọn nkan ti o sọ nipa wọn:

“Ẹyin ṣe afarawe wa, ati ti Oluwa, lẹyin ti ẹyin ti gba ọrọ naa ninu ọpọlọpọ ipọnju pẹlu ayọ Ẹmi Mimọ: Ti ẹyin si jẹ apẹẹrẹ fun gbogbo awọn ti o gbagbọ ni Masedonia ati Akaya. Nitori lati ọdọ yin lọ ni ọrọ Oluwa ti jade, kii ṣe ni kiki Masedonia ati Akaya nikan, ṣugbọn ni ibi gbogbo ni iyin igbagbọ yin si Ọlọrun tan kalẹ to bẹẹ ti awa ko ni iṣoro ohunkohun. Nitori pe awọn tikarawọn royin bi ẹ ti tẹwọ gba wa nigba ti a wa sọdọ yin, ati bi ẹyin si ti yipada si Ọlọrun kuro ninu ibọriṣa lati maa sin Ọlọrun alaaye ninu otitọ; Ti ẹ si n mura silẹ de bibọ ọmọ rẹ lati ọrun wa, ẹni ti o ji dide kuro ninu oku, ani Jesu naa, ẹni ti n gba wa kuro ninu ibinu ti n bọ.” (1Tẹsalonika 1:6-10)

Pẹlu nkan ti Pọọlu sọ ninu lẹta yi, daju ṣaka ni pe awokọsẹ rere ni ijọ Tẹsalonika jẹ fun awọn ijọ Ọlọrun miran ti o wa laye ni akoko yi. Ki lo si jẹ ki o ri bẹ? Nkan ti o jẹ ki o ri bẹ ni wipe wọn kọkọ yipada kuro ninu ibọriṣa patapata lati maa sin Ọlọrun alaaye ninu otitọ. Eyi tunmọ si pe wọn ko ma ṣe igbagbọ ko-ṣeku-ko-ṣẹyẹ. Wọn ko ma sin Ọlọrun ni ẹgbẹ kan, ki wọn si tun ma bọ oriṣa ni ẹgbẹ miran. Wọn ko ma si Ọlọrun ni ẹgbẹ kan, ki wọn si tun ma gbe igbe aye iṣẹkuṣe, ole jija, ajinigbe tabi apaniyan ni ẹgbẹ miran. Dipo eyi, kedere ni o han si gbogbo awọn ti o wa ni ayika wọn pe wọn ti fi ara wọn jin patapata fun Ọlọrun.

Yatọ si iyẹn, awọn ara yi tun bẹrẹ si ni gbe igbe aye ti o fihan gbogbo eniyan pe wọn n mura silẹ de Jesu Kirisiti. Eyi jasi pe wọn ko jẹ ki nkan ti aye yi kankan gba ọkan wọn tabi jọba lori wọn. Dipo eyi, nṣe ni wọn n ṣe afarawe awọn apọsiteli ti o waasu fun wọn ati Jesu Kirisiti Ọmọ Ọlọrun ti a waasu rẹ fun wọn. Nitorinaa, Ọlọrun wa bẹrẹ si ni lo wọn gẹgẹ bi apẹẹrẹ igbagbọ otitọ fun awọn ọmọ rẹ yoku ti o wa ni ayika wọn ati awọn alaigbagbọ pẹlu.

Nkan ti eyi si fi n han wa ni wipe Ọlọrun ko kan fẹ ki a di atunbi ninu Jesu Kirisiti nikan; O tun fẹ ki a bẹrẹ si ni gbe igbe aye ti yoo jẹ awokọṣe fun gbogbo awọn ti o ba wa ni ayika wa. Ṣe bayi ni o si wa ri fun wa? Ṣe awokọṣe onigbagbọ tootọ ni a jẹ gẹgẹ bi ijọ tabi gẹgẹ bi ẹnikọọkan fun awọn ti o wa ni ayika wa? Abi ṣe a kan n gbe igbe aye ti o wu wa ni, igbe aye ti ko ni itunmọ, igbe aye ti ko jọ wipe a mọ pe ohun gbogbo ko pin si aye yi ati pe Jesu Oluwa wa n bọ ni ọjọ kan lati mu wa si ọdọ rẹ ati lati ṣe idajọ aye yi?

O wa ṣeni laanu pe ọpọ awa ti a pe ara wa ni onigbagbọ loni ni a ko bikita rara nipa irufẹ igbe aye ti a n gbe ati ipa ti o n ko lori aye awọn ti o wa ni ayika wa. Ọpọ ninu wa si tun ni ko tilẹ fẹ gbọ pe Jesu n pada bọ wa rara. Eyi si n jẹ ki irufẹ igbagbọ ti a gba kọ eniyan lominu, yatọ si pe o n di itankalẹ ihinrere Jesu lọwọ laarin awọn alaigbagbọ.

Ọ̀RỌ́ ÌPARÌ Ni kukuru, lẹta yi n fi han wa pe ifẹ Ọlọrun fun wa ni pe ki a ma gbe igbe aye igbagbọ ti o n buyi fun orukọ Jesu, ti o n jẹ ki ihinrere Jesu wu awọn eniyan lati gbọ, ti o si tun ru awọn ọmọ Ọlọrun miran soke lati mu iduro ṣinṣin wọn ninu Kirisiti ni pataki.

ÌBÉÈRÈ – Kini pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

ALAYTHIA BIBLE CHURCH (ÌJỌ ÒTÍTỌ́ BÍBÉLÌ) ÀLÀKALẸ̀ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ ÀTI ÀLÀYÉ ỌJỌ́RÚ 01, ÒKÚDÙ 2022.

ÀKỌ́RÍ: ẸKỌ NINU IWE TẸSALONIKA KINNI Read More »