AYỌKA: 1TẸSALÓNÍKÀ 4:1-12 ÀKỌ́SÓRÍ: “”Nitori ẹyin tikarayin mọ, ara, pe ibẹwo wa si yin kii ṣe lasan.” (1Tẹsalonika 2:1)
Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ
Ninu ẹkọ ti a kọ pari ninu lẹta Pọọlu si awọn ara Tẹsalonika, a ri awọn ọna ti o gba ṣe pataki ki a mọ ipo ti awọn ọmọ Ọlọrun ti o wa ninu aye wa wa. Ninu ẹkọ eyi ti a mu yi, ẹwẹ, gbigbe igbe aye ti o wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun ni a fẹ ṣe agbeyẹwo. Bi Pọọlu ṣe fi ye wa, nigba ti wọn mu ọrọ Ọlọrun tọ awọn ara Tẹsalonika wa, wọn kọkọ kọ wọn bi a ti ṣe n gbe igbe aye ti o wu Ọlọrun, igbe aye ti o tẹ ẹ lọrun. O ṣi ṣe koko ki a kọ ẹnikẹni ti o ba ṣẹṣẹ n fi aye rẹ fun Jesu ni bi a ti ṣe n gbe igbe aye ti o tẹ Ọlọrun lọrun. Aijẹbẹ, a le ma ri iyatọ ninu igbe aye ti wọn n gbe tẹlẹ ati igbe aye ti wọn n gbe lẹyin igba ti wọn ti mọ Jesu. Idi niyi ti Pọọlu ṣe tun ran awọn ara Tẹsalonika leti ninu lẹta yi lara awọn nkan ti wọn kọ wọn nipa gbigbe igbe aye iwa mimọ, ki wọn ba tunbọ le tẹramọ. (Wo: 1Tẹsalonika 4:1)
ÌGBÉ AYÉ TÍ Ó TẸ́ ỌLỌ́RUN LỌ́RÙN
Irufẹ igbe aye wo ni o wa tẹ Ọlọrun lọrun? Gẹgẹ bi Pọọlu ti ṣe fi ye wa ninu lẹta yi, igbe aye ti o tẹ lọọrun jẹ:
– Ìgbé ayé àìléérí: Ninu lẹta yi, Pọọlu fi eyi han wa nipa ifẹ Ọlọrun fun gbogbo eniyan: “Nitori pe, ẹyin mọ aṣẹ ti a pa fun yin lati ọdọ Oluwa Jesu. Nitori ifẹ Ọlọrun ni pe ki ẹ jẹ mimọ, ki ẹ si yago kuro ninu ẹṣẹ agbere, ki ẹnikọọkan yin kọ lati sakoso ara rẹ ni ọna mimọ ati pẹlu ọla, ki i ṣẹ ni ifẹkufẹ gẹgẹ bi awọn alaikọla, ẹni ti ko mọ Ọlọrun; ati pe ninu ọrọ yi, ki ẹnikẹni yin ma ṣẹ kuna arakunrin rẹ nipa ohunkohun. Oluwa yoo jẹ eniyan niya fun gbogbo ẹṣẹ wọn, gẹgẹ bi a ti n sọ fun un yin tẹlẹtẹlẹ. Nitori Ọlọrun ko pe wa sinu aimọ, bi ko ṣe sinu igbe-aye mimọ. Nitori naa, ẹnikẹni ti o kọ ofin yii, ki i ṣe ofin eniyan ni ẹni naa kọ, bi ko ṣe ofin Ọlọrun ẹni ti o fi Ẹmi Mimọ rẹ fun ni.” (1Tẹsalonika 4:2-8) Bi apọsiteli yi ti ṣe la a kalẹ fun wa, a ri wipe igbe aye wa ko le tẹ Ọlọrun lọrun ti a ko ba yago fun agbere, pansaga, iwa eeri ati bẹẹbẹẹ lọ. Nitorina, ojuṣẹ ẹnikọọkan wa ni lati kọ bi yoo ṣe ko ara rẹ ni ijanu ni ọna ti o mọ, ti o si tun ni ọla, ko ki i ṣe ojuṣe Ọlọrun rara.
Bi itan Josẹfu ti lọ ninu bibeli, oun funrarẹ lo ko ara rẹ ni ijanu nigba ti iyawo oluwa rẹ, Pọtifa, bẹrẹ si ni fi ẹṣẹ agbere lọ ọ. Oun lo ba ara rẹ sọrọ pe ohun gbọdọ jina si arabinrin yi ati wipe oun gbọdọ sa fun ẹṣẹ agbere pẹlu rẹ, bi o ti wu ki nkan ri. Ọlọrun ran lọwọ lati jẹ ki eyi ṣeeṣe lotitọ. Amọ idi ti Ọlọrun fi ri ran lọwọ ni pe oun funrarẹ ti pinu lati ṣe ohun ti o tọ pẹlu agọ ara rẹ, ki o si ma ṣẹ si Ọlọrun ati ṣi ọga rẹ. Eyi n jẹ ki o ye wa pe awa naa gbọdọ pinu ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun fun wa lati takete tabi sa fun ẹṣẹ agbere nipa ki a ma fi aye gba ifẹkufẹ ninu ọkan wa ati nipa ki a ma fi anfaani silẹ fun ibaṣepọ ti ko tọ pẹlu awọn ti ko ki i ṣe aya tabi ọkọ wa. (Wo: Jẹnẹsisi 39; 1Kọrinnti 6:18)
Lotitọ, aye ti a wa yi jẹ eyi ti o kun fun oniruuru iwa idibajẹ. Idi si ni pe ọpọ lo fẹran iwa ibajẹ ati oniruuru iṣekuṣe. Wọn a si tun ma wa ọna lati mu awọn miran kunra ninu idibajẹ wọn, pẹlupẹlu ninu ijọ. Ti awọn ọmọ Ọlọrun ko ba wa fi si ọkan pe iṣekuṣe, agbere, pansaga ati awọn iwa eeri miran ti o fara pẹ wọn lodi si ifẹ Baba wọn ti O pe wọn, ti O si fi Ẹmi Mimọ rẹ sinu wọn, ko si ni ki wọn ma ba ara wọn jẹ pẹlu awọn idibajẹ aye yi. Ẹni ti o ba si ba ara rẹ jẹ ni ọna yi di dandan ki o ba ijiya pade lati ọwọ Ọlọrun nigba ti akoko ba to.
– Ìgbé ayé ìfẹ́: Yatọ si pe ki a ma fi iṣekuṣe ba ara wa jẹ, a tun gbọdọ fi ara wa jin lati fi ifẹ han si gbogbo awọn ti o ba wa ninu aye wa tabi ti a ba n ni ajọṣepọ pẹlu, lọna kan tabi omiran. Igbe aye ti ko ba si kun fun ifẹ Ọlọrun si awọn eniyan ko tẹ ẹ lọrun rara. Ki a tilẹ sọ otitọ, igbe aye asan, igbe aye ti ko lere ni igbe aye ti ko ba kun fun ifẹ Ọlọrun jẹ (1Kọrinnti 13). Idi si ni pe Jesu funrarẹ ti jẹ ki o ye wa pe nipa rinrin ninu ifẹ ni awọn eniyan yoo ṣe mọ wa gẹgẹ bi ọmọ ẹyin rẹ nitootọ (Johanu 13:34-35). Bi a ti ṣe mọ, a ri awọn ti ko gba Jesu gbọ rara ti ko ki i gbe igbe aye iṣekuṣe tabi agbere rara. Ki wa ni yoo jẹ iyatọ laarin iru awọn wọnyi ati awọn ọmọ Ọlọrun? Igbe aye ifẹ ni! Nitorina, awa ti a jẹ ọmọ Ọlọrun gbọdọ mọ pe ko to ki a yẹra fun ifẹkufẹ ati iwa eeri ninu aye yi; a tun gbọdọ tẹramọ igbe aye ifẹ. Pọọlu si fi eyi han wa ninu nkan ti o sọ fun awọn ara Tẹsalonika pe, “Ṣugbọn nipa ifẹ ara, a o ni lati tun kọwe si i yin, idi ni pe, Ọlọrun paapaa n kọ yin lati fẹran ara yin. Nitootọ, ẹ ni ifẹ fun awọn arakunrin ti o wa kaakiri Makidonia. Sibẹsibẹ awa n bẹ yin, ara, pe ki ẹyin ki o maa tẹsiwaju ninu rẹ.” (1Tẹsalonika 4:9-10) Bi a ti ṣe ri ninu ọrọ rẹ, Ọlọrun funrarẹ ni O kọ awọn ara Tẹsalonika lati ma rin ninu ifẹ nipasẹ Ẹmi Mimọ rẹ ti O fi fun wọn. O ṣi ṣetan lati kọ awa naa lati ma a rin ninu ifẹ nipasẹ Ẹmi Mimọ rẹ, ti a ba fi ara wa jin fun.
– Igbe aye ẹni ti o tojubọ: Nkan miran ti Pọọlu tun sọ fun wa ninu lẹta si awọn ara Tẹsalonika nipa igba aye ti O tẹ Ọlọrun lọrun ni pe o jẹ igbe aye ẹni ti o wulo, ẹni ti o to oju bọ, ti ko si nilo lati ko bukata aye rẹ le ẹnikẹni lori. Iwọ naa wo nkan ti o sọ nipa eyi: “Ẹ jẹ ki eyi jẹ ifẹ ọkan yin lati gbe jẹẹ ati lati mọ ti ara yin ati ki olukuluku kọju si iṣẹ rẹ, gẹgẹ bi a ti wi fun yin. Eyi yoo mu ki awọn ti ki i ṣe Kirisitẹni gbẹkẹle yin ati lati bu ọla fun yin pẹlu. Bi ẹ ba ṣe bẹẹ, ẹ ko ni maa wo oju ẹnikẹni lati fun yin ni owo ti ẹ o fi san gbese.” (1Tẹsalonika 4:11-12) Ki ni eyi n fi ye wa? Oun naa ni pe igbe aye aláìní, igbe aye onigbese, igbe aye atọrọjẹ ko ki i ṣe ifẹ Ọlọrun fun awọn ọmọ rẹ. Ko wu u tabi tẹ ẹ lọrun rara. Ko si fẹ ki a ma sọ wipe nitori Jesu ni aye wa ṣe ri bayi. Idi si niyi ti ko fi fẹ ki a ya ọlẹ, afàjọ̀ọ̀ tabi alainikanṣe. Dipo bẹẹ, O fẹ ki a yago fun abosi, igbesi aye imẹlẹ, ki a tẹra mọ iṣẹ wa, ki a si ma ṣe ni ọna ti a o fi ni anito ati aniṣẹku. Eyi jasi pe Ọlọrun ni lọkan lati bukun fun wa lọpọ yanturu, ti a ba tẹra mọ iṣẹ wa, ti a si n ṣe pẹlu ọgbọn ati oye ti o peye. Pọọlu si tun wa jẹ ki o ye wa pe ti a ba gbe aye wa lọna yi, a ko ni nilo lati ma woju ẹnikẹni fun ounjẹ tabi fun owo lati ṣe ojuṣe wa. Dipo eyi, nṣe ni awọn ti o wa ni ayika wa yoo ma bọwọ fun wa.
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Iwọ naa wo igbe aye ti o n gbe. Njẹ o ba ifẹ Ọlọrun mu bi? Ṣe igbe aye aileeri, igbe aye ifẹ ati igbe aye ẹni ti o toju bọ ni bi? Abi igbe aye iṣekuṣe, ikorira ati alaiwulo ni? Mọ lọkan rẹ pe Ọlọrun fẹ ki gbogbo awa ti a jẹ ọmọ rẹ mọ irufẹ igbe aye ti O tẹ ẹ lọrun, ki a si tun tẹramọ ati ma a gbe. Ẹnikẹni ti ko ba wa mọ eyi, ki o si mu ni pataki n fi ara rẹ han bi ẹni ti ko i ti ba Jesu pade rara tabi ti ko ni oye nkan ti a n pe ni igbe aye Kirisitiẹni.
Lati ọwọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)