ÀLÀKALẸ̀ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ ÀTI ÀLÀYÉ | ỌJỌ́RÚ 26, ÒWÀRÀ 2022
ÀKỌ́RÍ: Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ GÀLÁTÍÀ | ÀYỌKÀ: GÀLÁTÍÀ 3:6-5
ÀKỌ́SÓRÍ: “Emi ko sọ oore-ọfẹ Ọlọrun di asan: nitori pe, bi a ba ti ipasẹ ofin sọ eniyan di olododo, njẹ iku Kirisiti jẹ asan.” (Galatia 2:21)
Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ
Ninu ẹkọ ti a kọ kẹyin ninu lẹta Pọọlu si awọn ara Galatia, a ri awọn nkan ti o pe akiyesi wọn si nipa bi wọn ti ṣe bẹrẹ irina-ajo wọn pẹlu Ọlọrun ninu Kirisiti ati awọn ọna ti wọn gba ṣe aṣiṣe. O si pe akiyesi wọn si awọn nkan wọnyi lati jẹ ki wọn mọ pe aiṣe amulo ọpọlọ ti Ọlọrun fun wọn lati ṣe agbeyẹwo awọn ẹkọ odi ti a mu tọ wọn wa ni o jẹ ki wọn pa Jesu ti lati tẹle ofin Mose. Gẹgẹ bi o ti se sọ fun wọn, niwọn igba ti Ọlọrun ko kọ lati sọ wọn di ẹda titun, lati fun wọn ni Ẹmi Mimọ rẹ ati lati ṣe oniruuru iṣẹ ami ati iṣẹ iyanu laarin wọn nitoripe wọn ko tẹle ofin Mose, o yẹ ki wọn mọ pe wọn ko nilo lati pa ofin yi mọ lati di ẹni idalare niwaju rẹ. O wa jẹ iyalẹnu pe ọpọ loni naa ni o n rin ni ipasẹ ijọ Galatia, ti awọn naa ko woye pe wọn ko nilo lati pa ofin Mose mọ lati di ẹni idalare niwaju Ọlọrun, niwọn igba ti ko ki i ṣe nipasẹ ofin yi ni Ọlọrun ṣe tun wọn bi. Ti awọn naa ko ba si fẹ kuna oore-ọfẹ Ọlọrun lẹkan si, wọn nilo lati fi ara balẹ ka awọn nkan ti Pọọlu kọ sinu lẹta yi si awọn ara Galatia, ki wọn si bẹrẹ si ni ṣe amulo wọn.
BÍ A TÍ ṢE Ń DI ẸNI ÌDÁLÁRE
Lati wa fi idi nkan ti o kọ awọn ara Galatia ninu lẹta yi mulẹ gidigidi, Pọọlu tẹsiwaju latii fi Aburahamu ṣe apẹẹrẹ bi eniyan ṣe n di ẹni idalare niwaju Ọlọrun fun wọn. Iwọ naa wo lara awọn nkan ti o sọ lori eyi:
“Gẹgẹ bi Aburahamu ti gba Ọlọrun gbọ, ti a si ka a si olododo eniyan. Bẹẹ ni, ki ẹyin ki o mọ pe, awọn tii ṣe tii igbagbọ, awọn naa ni i ṣe ọmọ Aburahamu. Bi iwe-mimọ si ti wi tẹlẹ pe, Ọlọrun yoo da awọn keferi lare nipa igbagbọ, Ọlọrun ti waasu iyinrere yii ṣaaju fun Aburahamu, pe, nipasẹ rẹ ni oun yoo bukun gbogbo eniyan. Gẹgẹ bẹẹ ni awọn ẹni ti o gbagbọ pẹlu jẹ alabakun-fun pẹlu Aburahamu olododo. Nitori pe iye awọn ti o gbẹkẹle iṣẹ ofin n bẹ labẹ egun: nitori ti a ti kọ ọ ninu iwe mimọ pe, Ọlọrun yoo fi ẹnikẹni ti ki i ṣe gẹgẹ bi ohun gbogbo ti a kọ sinu iwe ofin bu. Nitori o damiloju pe, a ko da ẹnikẹni lare niwaju Ọlọrun nipa ṣiṣe gẹgẹ bi ofin nitori pe, olododo yoo ye nipa igbagbọ. Ofin ki i ṣi i ṣe ti igbagbọ ṣugbọn ẹni ti n ṣe wọn yoo ye nipasẹ wọn. Kirisiti ti ra wa pada kuro lọwọ egun ofin, ẹni ti a fi ṣe egun fun wa nitori ti a ti kọ ọ ninu iwe-mimọ pe, Ẹnikẹni ti a gbe kọ sori igi n bẹ labẹ egun Ọlọrun: Ki ibukun naa, eyi ti Ọlọrun ṣe ileri rẹ fun Aburahamu le jẹ ti awọn Keferi nipa Kirisiti Jesu; ki awa ki o le gba ileri Ẹmi nipa igbagbọ.” (Gàlátíà 3:6-14)
Ki ni awọn koko ti Pọọlu fẹ ki awọn ara Galatia ati awa naa pẹlu dimu pẹlu awọn nkan ti o sọ nibiyi? Akọkọ ni pe Aburahamu ti o jẹ baba nla awọn Juu, ti o si jẹ apẹẹrẹ ẹni idalare niwaju Ọlọrun di ẹni idalare niwaju rẹ nipa igbagbọ dipo nipa ofin tabi nipa iṣẹ rere rẹ. Bibeli sọ wipe, “Aburamu si gba Ọlọrun gbọ, a si ka a si ododo fun-un.” (Jẹ́nẹ́sísì 15:6) Njẹ o ri bayi? Ko ki ṣe iṣẹ rere Aburahamu ni Ọlọrun wo lati tẹwọgba tabi lati ka si olododo tabi ẹni idalare niwaju rẹ. Lotitọ, Aburahamu ni awọn iṣẹ rere ti a le tọkasi tabi ti o le fọnnu nipa wọn. Amọ awọn eleyi ko jamọ nkankan niwaju Ọlọrun. Yatọ si eyi, Aburahamu naa tun ni awọn aiṣedede ati aiṣodo tirẹ, ti a tilẹ kọ sinu bibeli fun ẹkọ wa. Ti Ọlọrun ba wa ṣe idajọ rẹ lori awọn nkan wọnyi, ko ni i ka si olododo rara. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 12; Jẹ́nẹ́sísì 16; Jẹ́nẹ́sísì 20; Róòmù 4:1-3)
Amọ Ọlọrun ka Aburahamu si olododo. Ki si ni idi? Idi ni pe o gba ọrọ Ọlọrun gbọ. Nibakana, ẹnikẹni ti Ọlọrun yoo ba tẹwọgba gẹgẹ bi olododo tabi ka si ẹni idalare gbọdọ gba ọrọ rẹ gbọ lori igbala ọkan rẹ. Ki si ni ọrọ rẹ lori igbala ọkan wa? Ohun naa ni pe ki a gba Jesu ni Oluwa wa, a o si gba wa la, a o si tun sọ wa di ẹni itẹwọgba niwaju rẹ (Ìṣe Àpọ́sítélì 16:29-31; Róòmù 10:9-10). Awọn ti o ba si wa ṣe bẹẹ gẹgẹ ni Pọọlu tọka si gẹgẹ bi ọmọ Aburahamu tootọ.
Koko ẹkọ keji ti Pọọlu n fi ye wa ninu awọn ẹsẹ bibeli yi ni pe nitori igbagbọ Aburahamu, Ọlọrun ba da majẹmu pe nipasẹ rẹ ni Oun O ti ṣe bukun fun gbogbo araye (Jẹ́nẹ́sìsì 12:1-3 &22:15-18). Eyi wa tunmọ si pe gbogbo awọn ti o ba jẹ ọmọ Aburahamu ni o jẹ ẹni ibukun ti Ọlọrun yoo lo lati ma bukun fun gbogbo awọn ti o ba wa ni ayika wọn. Ṣe eyi wa jasi pe gbogbo awọn Juu ti o jẹ arọmọdọmọ Aburahamu ni ọrọ yi n tọka si bi? Rara o!
Lotitọ, arọmọdọmọ Aburahamu ni awọn Juu jẹ. Awọn ni o si tọ si lati jẹ ere ileri Ọlọrun yi. Ṣugbọn ofin Mose ti a fun wọn ti ba nkan jẹ. Idi si ni pe ofin Mose fi wọn si abẹ egun, gẹgẹ bi Pọọlu ti ṣe fi ye wa. Ofin Mose sọ gbangba-gbangba pe egun ni fun ẹnikẹni ti ko ba pa gbogbo nkan ti o wa ninu iwe ofin yi mọ (Ditarónómì 27:26). Niwọn igba ti ko si si ẹni naa ti o le pa gbogbo awọn nkan ti a kọ sinu iwe ofin Mose mọ, lalai yẹsẹ, a jẹ wipe gbogbo awọn ọmọ Isiraẹli ni o wa labẹ egun niyẹn.
Bawo wa ni awọn ọmọ Isiraẹli yoo ṣe wa wa labẹ egun ofin Mose ti Ọlọrun yoo si tun lo wọn lati bukun fun gbogbo araye? Ko ṣeeṣe. Ayafi ti a ba yọ wọn kuro labẹ egun yi nikan ni eyi yoo ṣe ṣeeṣe. Idi niyi, bi Pọọlu ṣe fi ye wa, ti a fi kan Jesu mọ agbelebu fun wa. Jesu, gẹgẹ bi ẹbọ fun ẹṣẹ gbogbo araye, le gba oniruuru ọna ku. Ṣugbọn iku ori igi agbelebu ni o ku. Awọn Juu gan funran wọn ni wọn sọ fun Pilatu pe nṣe ni ki o kan an mọ agbelebu. Ki ni idi? Idi ni pe Ọlọrun fẹ ki O di egun fun wọn, ki wọn ba le bọ kuro labẹ egun ofin Mose.
Ofin Mose sọ eyi fun wa nipa ẹnikẹni ti a ba gbe kọ sori igi: “Bi ọkunrin kan ti o jẹbi ẹsun ba ni lati ku ti o si ku, ti a si gbe oku rẹ kọ sara igi, o ko gbọdọ fi oku rẹ silẹ sara igi ni gbogbo oru. Gbiyanju lati sin in ni ọjọ naa gan an, nitori ẹni ti a ba gbekọ sori igi wa labẹ egun Ọlọrun. O ko gbọdọ ba ilẹ ti Oluwa Ọlọrun rẹ fun ọ gẹgẹ bi ogun jẹ.” (Ditarónómì 21:23) Ṣe o ri bayi? Nigba ti a kan Jesu mọ ori igi, ara nkan ti o ṣẹlẹ si ni pe o di egun fun gbogbo awọn Juu ti o wa ni abẹ egun ofin Mose. Eyi si ni o jẹ ki o ṣeeṣe fun Ọlọrun lati tu ibukun Ẹmi mimọ rẹ lẹyin iku, ajinde ati igbasoke rẹ sori awọn ti o gbagbọ, akọkọ awọn Juu ati lẹyin eyi awọn Keferi.
Nkan ti a n sọ ni pe, niwọn igba ti Ọlọrun ko i ti mu egun ofin Mose kuro lori awọn ọmọ Isiraẹli, ko le tipasẹ wọn bukun fun ẹnikẹni laye yi. Ṣugbọn ni kete ti O mu egun yi kuro nipa iku Jesu lori igi agbelebu, a ri wipe O tu Ẹmi mimọ rẹ sori awọn Juu ti o jẹ ọmọlẹyin Jesu. Lati igba naa lọ si ni o ti bẹrẹ si ni ti ipasẹ wọn bukun fun awọn Keferi ti o ba gbọgbọ nipa fifun wọn ni ẹbun ọfẹ Ẹmi mimọ rẹ lati tun wọn da ati lati ma gbe inu wọn titi lailai. Gbogbo awọn ti o si wa tipasẹ eyi di alabukunfun naa ni o wa ni ipo ẹni ti Ọlọrun le lo lati bukun fun awọn yowu ti o ba wa ni ayika wọn ti wọn ba gbagbọ.
Niwọn igba ti eyi si ri bẹ, ko wa yẹ ki a ri Kirisitiẹni kankan, yala Juu ni tabi Keferi, ti yoo tun mura tan lati fi ara rẹ si abẹ egun ofin Mose. Amọ o ṣeni laanu pe ailoye nkan wọnyi ti jẹ ki ọpọ fi ara wọn si abẹ egun ti Ọlọrun ko fi wọn si, ti wọn si wa fi aye silẹ fun Satani lati ma pọn wọn loju ati lati jẹ ki o ṣoro fun wọn lati gbe igbe aye ti o tẹ Ọlọrun lọrun. Boya iwọ na tilẹ wa lara awọn ti o fi ara wọn si abẹ egun ofin Mose nipa fifẹ pa awọn abala ofin yi kan mọ. Aṣiṣẹ nla gba ni eyi jẹ nitori ẹnikẹni ti o ba fẹ ṣe amulo ofin Mose gbọdọ ṣe amulo gbogbo rẹ. Aijẹbẹ, nṣe ni yoo fi ara rẹ si abẹ egun ofin naa, ti ko si ni wulo fun Ọlọrun lati lo lati mu ifẹ rẹ ṣẹ ninu aye awọn eniyan. Nitorina, yọ ara rẹ kuro labẹ egun ti Ọlọrun ko fi ọ si, ki o si jẹ ki igbagbọ rẹ ninu Jesu ati iku, ajinde ati igbasoke rẹ to fun ọ.
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Igbagbọ ninu Ọlọrun ati ọrọ rẹ nikan ni o le sọ wa di ẹni igbala ati idalare niwaju rẹ. Ọna ti Aburahamu gba di ẹni idalare ni eyi. Ọna yi kanna si ni gbogbo awọn ti o ba gbagbọ ninu Ọlọrun ati ninu ọmọ rẹ Jesu Kirisiti, ẹni ti o ku fun ẹṣẹ wa, yoo ṣe gba di ẹni igbala ati idalare, gẹgẹ bi Aburahamu. Kirisitiẹni ti o ba wa kọ ọna yi silẹ lati tẹlẹ ofin Mose n fi ara rẹ si abẹ egun ofin yi ni, egun ti Jesu ti ku lati mu kuro lori awọn Juu ti a gbe ofin yi le lọwọ. O si di dandan ki iru ẹnibẹ ṣubu kuro ninu oore-ọfẹ Ọlọrun, ki o si di iṣẹ Ẹmi mimọ ninu ati lori aye rẹ lati sọ di ẹni ti Ọlọrun fẹ ki o jẹ lọwọ.
ÌBÉÈRÈ
- Bawo ni ẹkọ yi ṣe wulo si fun awọn ọmọ Ọlọrun loni ti oye iha ti o yẹ ki wọn kọ si ofin Mose ko ye?
Lati ọwọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)