Wọn kò ní dúró bèrè àyè tàbí gba àṣẹ lọ́wọ́ rẹ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 27, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 30
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu ọdun yi. Adura mi ni pe ki a fun ọkan rẹ ni okun ati irẹlẹ lati fi aye gba Ọlọrun lati gba iṣakoso aye rẹ patapata, ki o ba le jẹ pe iṣẹ rẹ nikan, ti ko si ni jẹ iṣẹ Satani, ni yoo ma jẹyọ ninu aye rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.
Ninu iwe Ifihan, ori ikẹta, ẹsẹ ogun, Johanu fi igbe rara Jesu Oluwa wa si ijọ awọn ara Laodikia han wa, eyi ti o ka bayi: “Kiyesi i, emi duro ni ẹnu ilẹkun, emi si n kankun, bi ẹnikẹni ba gbọ ohun mi, ti o si ṣi ilẹkun, emi yoo wọle tọ ọ wa, emi yoo si maa ba a jẹun, ati oun pẹlu mi.” (Ifihan 3:20) Kini nkan ti o le fa ki Oluwa wa ma kan ilẹkun aye Kirisitẹni? Ṣe Oun kọ ni Oluwa wa ni? Oun ni! Ati wipe, gẹgẹ bi Oluwa wa, ṣe ko ki i ṣe inu aye wa ni O yẹ ki O wa, ki O si ma ṣe akoṣo ohun gbogbo? Inu rẹ ni O yẹ ki o wa! Ki wa lo de ti O tun ṣe nilo aṣẹ ati ifọwọsowọpọ wa lati wole sinu abala aye wa kan tabi omiran lati ba wa lo pọ nibẹ?
Idi naa ko ruju rara. Oluwa ko ki i ti ara rẹ mọ eniyan lọrun. Dipo eyi, nṣe ni yoo fi aye gba wọn lati ro wo funralara wọn lati pinu boya wọn nilo rẹ ninu aye wọn tabi wọn ko nilo rẹ, ki wọn si gbe igbesẹ ni ibamu pẹlu ero wọn. Eyi si ni alaye fun bi gbogbo agbaye ko ti se di ẹni igbala. Oluwa ko ni fi dandan mu wa tẹwọgba igbala rẹ. A wa ni a nilo lati gba pe a nilo igbala ati pe a ko le gba ara wa la kuro lọwọ awọn nkan ti o n pa wa run ti Oun ko ba gba wa la.
Amọ ṣa o, ọtọ n ki a wa sọdọ Oluwa fun igbala, ọtọ ṣi tun ni ki a fi aye gba lati gba wa la patapata ati lati pa wa mọ titi lailai. Bawo ṣi ni eyi yoo ṣe ṣeeṣe? Yoo ṣeeṣe nipa fifi aye gba lati dari wa ninu gbogbo abala aye wa, lalai fi ọkankan pamọ fun. Gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun, inu wa ni O n gbe, nitori pe tẹmipili rẹ ni a jẹ. Ṣugbọn pe O n gbe inu wa ko tunmọ si pe O n ṣe iṣakoso aye wa ati ọrọ aye wa. Pe O n gbe inu wa ko tunmọ si pe ko ni nilo lati kan ilẹkun awọn abala aye wa kan naa lati ri boya a o fi aye gba lati ṣe akoso wọn.
Gbogbo wa la mọ ara wa. Gbogbo wa ni a mọ boya a fi aye gba Jesu Oluwa wa lati ṣe akoso gbogbo aye wa tabi bẹẹ kọ. Gbogbo wa la mọ awọn abala aye wa ti a ti ti ilẹkun mọ patapata nitori pe a ko fẹ gbọ ohunkoun ti O fẹ sọ fun wa nipa wọn tabi nitori pe a gbagbọ pe a koju oṣuwọn lati moju to wọn. Nkan ti a wa le ma mọ ni pe Jesu Oluwa wa ko ku fun wa ki O ba le jẹ Oluwa lori awọn abala aye wa melokan. Dipo eyi, nṣe ni O ku fun wa lati jẹ Oluwa lori gbogbo abala aye wa.
Lafikun, Jesu Oluwa wa ko gba wa la lọwọ Eṣu ati awọn ogun rẹ ki O ba le jẹ Oluwa lori abala aye wa melokan. Dipo eyi, O gba wa la ki O ba le jẹ Oluwa lori gbogbo abala aye wa. Nitorina, ti a ko ba ni finufẹdọ gba a laaye lati jẹ alakoso gbogbo abala aye wa, ti a ba ti ilẹkun aye wa tabi ilẹkun awọn abala aye wa kan mọ, nitori pe ko ni ti ara rẹ mọ wa lọrun, nṣe ni ki a bẹrẹ si ni fojusọna fun awọn ọta ọkan wa ti O gba wa la lọwọ wọn lati lo anfaani yi lati pada wa sinu aye wa ati lati tun iṣẹ wọn ṣe. Awọn wọnyi ko wa ni kan ilẹkun tabi duro gba aye lọwọ wa ti wọn ba fẹ wọlẹ. Nṣe ni wọn yo wọlẹ boya a fun wọn ni aye tabi a ko fun wọn ni aye.
Iwọ naa wo nkan ti Jesu Oluwa wa sọ nipa eyi: “Nigba ti ẹmi buburu kan ba jade lara eniyan, a maa rin ni aṣalẹ, a maa wa ibi isinmi, ko si ni ri i. Nigba naa ni ẹmi yoo wi pe, ‘Emi yoo pada si ara ọkunrin ti emi ti wa.’ Bi o ba si pada, ti o si ba ọkan ọkunrin naa ni ofifo, a gba a mọ, a si ṣe e ni ọsọ. Nigba naa ni ẹmi esu naa yoo wa ẹmi meje miiran ti o buru ju oun lọ. Gbogbo wọn yoo si wa si inu rẹ, wọn yoo maa gbe ibẹ. Igbẹyin ọkunrin naa a si buru ju ti iṣaaju lọ; Bẹẹ gẹgẹ ni yoo ri fun iran buburu yii pẹlu.” (Matiu 12:43-45) Njẹ o ri bayẹn? Nṣe ni Eṣu ati awọn ẹmikẹmi rẹ ma n fi gbogbo igba wa bi isinmi. Idi kan ṣoṣo ti wọn ko si fi ni ri aye fi aye wa tabi abala aye wa kankan ṣe ile tabi ibi isinmi ni ki wọn ri pe Jesu Oluwa wa ti n gbe ibẹ, ti O si tun n ṣe akoso ibẹ.
Ṣugbọn ti wọn ba wa bẹ aye wa wo, ti wọn ri pe wọn ṣofo tabi pe awọn abala kan ninu wọn ṣofo, ti wọn ko si si ni abẹ iṣakoso ẹnikan ṣoṣo ti O ni aṣẹ ati agbara lori wọn, wọn ko ni fi akoko ṣofo rara lati ko ara wọn jọ lati gba iṣakoso abala aye wa yi. Nṣe wa ni nkan yoo bẹrẹ si ni buru si fun wa ni abala aye wa naa. Ti a ba si tun wa lọra lati tete jẹ ki Oluwa wọle, ki O si gba iṣakoso rẹ, ko ni pẹ rara ti iṣẹ ibi awọn ẹda buburu yi yoo fi tan de awọn abala aye wa miran.
Wayi o, boya iru ipo ti o wa niyi. Dipo ki nkan ma san si fun ọ ni awọn abala aye rẹ ti o ti n ba idojukọ pade, ko ki ṣe wipe o kan n buru si nikan, nṣe ni ibajẹ naa tun ti wa n tan wọnu awọn abala aye rẹ yoku ti o ti wa ni alaafia tẹlẹ. O wa yẹ ki o yẹ ara rẹ wo lati mọ boya o ti ti Jesu sita kuro ninu awọn abala aye rẹ kan. Ti eyi ba si ri bẹ, ọna abayọ kan ṣoṣo ti o wa fun ọ naa ni ki o ronupiwada, ki o si ṣi ilẹkun fun lalai fi akoko ṣofo, ki O ba le ṣe nkan ti o jẹ wipe Oun nikan naa ni O le ṣe, ki O si da alaafia ati ayọ rẹ pada. Ṣugbọn ti o ba ṣe orikunkun, ti o si duro lori pe o ni i fi aye gba iṣakoso rẹ lori gbogbo aye rẹ, nṣe ni ki o mura lati tẹwọgba pupọ iṣẹ Satani si ninu aye rẹ ati lori ọrọ aye rẹ, boya o fun ni aye tabi o ko fun ni aye.
Ki o ni ọsẹ alarinrin.
Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)



