Ẹ ṣààmì sí wọn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ṣẹrẹ 22, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 39
Olufẹ: Ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lailodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu idunnu ni mo ki ọ kaabọ sinu ọṣẹ miran lọdun yi. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun jẹ ki ọkan rẹ wa ni pipe ati ni irẹlẹ niwaju rẹ ni gbogbo igba, ki o ma ba ni iriri iṣubu kankan ṣugbọn iriri igbega lọdun yi, ni orukọ Jesu. Amin.
Bi bibeli ti ṣe sọ fun wa, igberaga jẹ ọkan pataki lara awọn idi ti awọn eniyan fi ma n ni iriri iṣubu tabi ti a fi ma n di wọn lọwọ lati ni iriri igbega laye yi. Ti a ba si wa n rin ninu igberaga, a je wipe o ṣeeṣe ki a bi wa lulẹ lati ipo atata yowu ti a le wa tabi ki a ma jẹ ki a gberi kọja ibi ti a wa laye. Nitorina, ṣọra fun oniruuru igberaga, ki o si ri wipe o ko fi aye gba ọkankan ninu wọn lati fi gbongbo mulẹ ninu aye rẹ. (Wo: Iwe Owe 16:18; Jemisi 4:6-7; 1Peteru 5:5-6)
Wayi o, ọkan lara oniruuru igberaga ti awọn ọmọ Ọlọrun ko ki i tete damọ, ṣugbọn ti o si wa ninu ọpọlọpọ wa, ni o ni i ṣe pẹlu aigbọran si awọn alaṣẹ nipa ti ẹmi. Ti mo ba si n sọrọ nipa awọn alaṣẹ nipa ti ẹmi, mo n sọrọ nipa awọn ti Ọlọrun yan le ọ lori ninu ijọ rẹ. Awọn wọnyi ni O yan lati bọ ọ pẹlu ọrọ rẹ ati lati ma ṣọna lori ọkan rẹ nipa adura gbigba ati ibaṣepọ igbagbọ. Nitorina, nkan ti mo n sọ kọ nipe gbogbo pasitọ, wolii, ajinyinrere tabi apọsiteli ti o ba pade naa ni adari ẹmi fun ọ, ti o si gbọdọ gbọran si lẹnu.
Ti eniyan ko ba ki i ṣe adari ninu ijọ rẹ, ko pọn dandan fun ọ lati tẹle aṣe yowu ti o ba pa fun ọ, yala o dara tabi ko dara, ti ko ba ki i ṣe pe ẹ ti jọ ni ajọsepọ tẹlẹ, ti o si tun mọn-ọn si ẹni ti o le fọkantan. Ṣugbọn ti eniyan ba jẹ adari ijọ rẹ, o pọn dandan fun ọ lati gbọran si aṣẹ rẹ, niwọn igba ti awọn aṣẹ naa ba ti wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun. O wa ṣeni laanu pe ọpọ igba ni a ma n ri awọn ọmọ Ọlọrun ti wọn n bu ọla ti o ga fun awọn adari ijọ ti a ko yan le wọn lori nigba ti wọn a si ma tabuku awọn ti a yan le wọn lori ninu ijọ wọn.
Ṣugbọn eyi ko tọna rara, o si tun lodi si ifẹ Ọlọrun fun aye wa. Pọọlu, nigba ti o n ba awọn ara Kọrinnti sọrọ lori nkan wọnyi, sọ wipe niwọn igba ti wọn n ran awọn adari ijọ kan ti ko si lori awọn ijọ wọn lọwọ, ti wọn si tun n bọwọ fun wọn, ṣe ko wa yẹ ki wọn ran oun tikararẹ lọwọ, ki wọn si tun bọwọ fun ju awọn wọnyi lọ, niwọn igba ti o jẹ pe oun ni baba wọn ninu igbagbọ ati pe ko fi igba kankan dẹkun lati ma sin wọn pẹlu ọrọ Ọlọrun ati adura? O yẹ bẹẹ. (Wo: 1Kọrinnti 9:11-12)
Nibakanna, ti o ba rọ iwọ naa lọrun lati ran awọn adari ijọ kan ti ko ma ṣọna le ọ lori ninu igbagbọ tabi ti o ko tilẹ ti fi igba kankan pade lọwọ ati lati bọwọ fun wọn, ṣe o wa yẹ ki o ṣoro fun ọ lati bọwọ fun awọn adari ijọ rẹ ti o n fi gbogbo igba sin ọ ati lati ran wọn lọwọ ju awọn wọnyẹ lọ? Ni kukuru, ara idi ti a fi ma n ri awọn adari ijọ wa fin lọna yi ni igberaga. Nigba ti a ba woye pe adari ijọ kan ko ni imọ to tabi dagba to tabi jafafa to tabi ka iwe to lati paṣẹ fun wa tabi dari wa, a ko ni gbọran si lẹnu tabi mu ni pataki.
Lafikun, ti a ko ba ni imọ ewu ti o sorọ mọ ki a ma gbọran si awọn adari ijọ wa lẹnu tabi ki a ma ri wọn fin, ọpọ ninu wa ninu ijọ loni si ni ko ni imọ awọn nkan wọnyi, o ṣeeṣe ki a ma ṣe aigbọran si wọn lẹnu tabi ki a ma tabuku wọn bi o ti ṣe wu wa. Ṣugbọn bi a ti ṣe ri ninu Iwe mimọ, ewu buruku lo sọrọ mọ ki a ma tabuku awọn adari wa ninu ẹmi tabi ki a ma kọ awọn eniyan lati ṣe orikunkun si wọn, bi o ti wu ki awọn adari yi kere lọjọ ori to tabi jẹ ẹni ti ko láapan to. Nitorina, ki ara rẹ nílọ̀ lórí awọn nkan yi. Aijẹbẹ, o le ma pẹ rara ti wa a fi ko ara rẹ sinu iyọnu ti Ọlọrun ko ni ko ọ yọ ninu rẹ. (Wo: Numeri 12&17)
Ni akotan, Pọọlu sọ eyi fun wa nipa bi o ti yẹ ki a ma ṣe si awọn ti ko ba mu awọn adari wa ninu ijọ ni pataki: “Bi ẹnikẹni ko ba si pa ofin wa ninu lẹta yii mọ, ẹ ṣaami si ẹni naa. Ẹ ma ṣe ba a kẹgbẹ ki oju ba a le ti i. Ṣibẹ, ẹ ma ṣe kaa si ọta, ṣugbọn ẹ maa kilọ fun-un gẹgẹ bi arakunrin yin.” (2Tẹsalóníkà 3:14-15) Njẹ o ri bayi? A sọ fun wa pe ki a ṣaami si ẹnikẹni ninu ijọ wa ti ko ba mu awọn adari wa ni pataki, ti o n sọrọ si wọn bi o ti ṣe wu tabi ti o n kọ awọn eniyan lati kọ etí ikún si aṣẹ wọn. Ki si ni idi? Akọkọ, ki a ba le kilọ fun wọn. Ekeji, ki a ba le yẹra fun wọn ti wọn ko ba gbọ ikilọ. Aijẹbẹ, awa funrawa le jẹ alabapin ninu ewu ti o sorọ mọ aigbọran wọn lẹyin-ọ-rẹyin.
Nitorina, ma fi gbogbo igba kiyesi bi awọn ti o n baa rin ninu ijọ ti ṣe n ṣe si awọn adari yin ninu ẹmi, bi o ti wu ki o fẹran wọn to. Eyi ni yoo jẹ ki o mọ boya wọn yoo busi idagbasoke rẹ ninu ijọba Ọlọrun tabi boya wọn yo lọwọ si iṣubu rẹ. Njẹ ki Ọlọrun kun ọ fun oye, okun ati igboya ti o peye lati ṣe eyi, ni orukọ Jesu. Amin.
Ki o ni ọsẹ atata.
Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)



