February 2023

Rẹ ara rẹ sílẹ̀ láti tẹ́wọ́gbà á | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èrèlé 26, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 43

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia di pupọ si fun ọ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti so oṣu Èrèlé ati oṣu Ẹrẹ́nà mọ ara wọn. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun jẹ ki ọkan rẹ ma fi gbogbo igba tẹ́wọ́gba ọrọ rẹ ti O sọ silẹ fun igbala ọkan rẹ pẹlu irẹlẹ. Amin.

Ninu ẹpisiteli rẹ, Jèmíìsì sọ eyi fun wa nipa ọrọ Ọlọrun ati nipa iha ti o yẹ ki a kọ si: “Nitori naa, ẹ lepa lati bori gbogbo eeri ati iwa buburu ti o gbilẹ yika, ki ẹ si fi ọkan tutu gba ọrọ naa ti a gbin ti o le gba ọkan yin la.” (Jákọ́bù 1:21) Ki ni o yẹ ki a ṣe pẹlu ọrọ Ọlọrun ti a n gbin sinu ọkan wa? Gẹgẹ bi apọsiteli yi ti ṣe wi, nṣe ni o yẹ ki a tẹwọgba pẹlu irẹlẹ. Eyi tunmọ si pe niwọn igba ti nkan ti o n tọ wa wa ba ti jẹ ọrọ Ọlọrun, a ko gbọdọ kọ ọ silẹ, gbe ju sẹgbẹkan tabi ba a jiyan. Dipo eyi, nṣe ni o yẹ ki a tẹwọ gba a pẹlu irẹlẹ, pẹlu imoye pe bi ọrọ rẹ tilẹ da bi ọrọ omugọ leti wa, agọ̀ Ọlọrun ṣi gbọn ju ọgbọn wa lọ. (Wo: 1Kọ́ríntì 1:25)

Idi wo wa ni o ṣe yẹ ki a fi irẹlẹ tẹwọgba ọrọ Ọlọrun, bi Jemiisi ti ṣe sọ fun wa? Idi naa ni pe ọrọ naa le gba ọkan wa la. Ọrọ Ọlọrun ni agbara lati gba wa la kuro lọwọ aye ibajẹ yi ati kuro lọwọ gbogbo ete eṣu lati pa wa run. Ṣugbọn a ko ni ni iriri agbara igbala ọrọ rẹ ti a ko ba fi irẹlẹ tẹwọ gba a, ki a si tun ṣe amulo rẹ.

O wa ṣeni laanu pe ọpọ ti o pe ara wọn ni ọmọ Ọlọrun, ti wọn si n gbọ ọrọ rẹ loorekoore ni ko ko ki rẹ ara wọn silẹ lati tẹwọ gba a ati lati ṣe amulo rẹ. Ki si ni idi? Idi ni pe wọn gberaga. Wọn ro wipe awọn gbọn tabi jafafa ju Ọlọrun lọ ati wipe awọn le mojuto ara wọn lalai fi tirẹ ṣe. Ṣugbọn ṣe a ri ẹni naa lara wa ti o gbọn bi Ọlọrun ẹlẹda wa? Ṣe a ri ẹni naa ti o le mojuto ọrọ aye rẹ funrarẹ lalai ma pa a run nikẹyinkẹyin? Ko si ẹni naa lara wa ti o dangajia fun eyi.

Amọ igbakigba ti a ba kọ ohun ti Ọlọrun n sọ fun wa silẹ, ti a si yan lati ṣe bi a ti ṣe fẹ, nkan ti a n sọ ni pe a lọpọlọ ju u lọ ati wipe a ko nilo itọni tabi ipese rẹ. Ibi yowu ti eyi ba si ti ri bẹ ẹ, o di dandan ki igbala fo wa ru. Eyi si ni alaye fun bi a ti ṣe ri ọpọ ọmọ Ọlọrun ti ko kuro loju kanna fun ọpọ ọdun tabi ti ko ni iriri igbala kuro lọwọ awọn iṣẹ eṣu kan ninu aye wọn. Wọn n fi gbogbo igba gbọ ọrọ Ọlọrun ṣugbọn wọn ko fi irẹlẹ tẹwọ gba a. Nitorina, ọrọ naa ko le e gba wọn la.

Boya bi nkan si ṣe ri fun iwọ naa ni eyi. Boya idi ti ọrọ Ọlọrun ko fi ma a ṣiṣẹ ninu aye rẹ ni pe iwọ naa ko rẹ ara rẹ silẹ lati tẹwọ gba a ati lati ṣe ohun ti O n sọ fun ọ nipa aye rẹ, igbagbọ rẹ, iṣẹ rẹ, okowo rẹ, ẹkọ rẹ, igbeyawo rẹ, ilera rẹ, eto isuna rẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ. A jẹ wipe o nilo lati ronupiwada, ki o si yi ọna rẹ pada niyẹn. Ki ni láríjà ki o ma lo ọpọlọpọ wakati lọsọọsẹ lati gbọ ọrọ ti o ko ni ṣiṣẹ le lori? Ṣe ko kuku san ki o ma gbọ rara?

Ni kukuru, ti a ba fẹ sọ otitọ, ki o ma gbọ ọrọ Ọlọrun rara buru ju ki o gbọ ki o ma mulo lọ. Idi si ni pe gbogbo anfaani lati di ẹni igbala ni ipasẹ rẹ ni iwọ yoo ti ti ilẹkun rẹ mọ ara rẹ. Nitorina, o nilo lati tẹsiwaju lati ma gbọ ọrọ rẹ. Ṣugbọn iyẹn ko to fun ọrọ yi lati ṣiṣẹ ninu aye rẹ. Fun un lati ṣiṣẹ ninu aye rẹ ati lati ya ọ ya ainitẹsiwaju ati iparun, o nilo lati rẹ ara rẹ silẹ lati tẹwọ gba a ati lati ṣe amulo rẹ. Adura mi si ni pe ki ọkan rẹ gba okun lati ma fi gbogbo igba ṣe eyi, ni orukọ Jesu. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ tí ó dára.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Rẹ ara rẹ sílẹ̀ láti tẹ́wọ́gbà á | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èrèlé 26, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 43 Read More »

Tí ààyò Ọlọ́run bá le kùnà | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èrèlé 19, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 42

Àkórí: Tí ààyò Ọlọ́run bá le kùnà
Láti ọwọ́: J.O. Lawal
Ọjọ́: Èrèlé 19, 2022
Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀
Nọ́múbà: Vol. 11, No. 42

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Èrèlé 2023. Mo gbadura pe ki Ọlọrun jẹ ki alaafia rẹ jọba ninu aye wa ati ni ibi gbogbo ni orilẹ-ede yi ninu gbogbo ọsẹ naa, ni orukọ Jesu. Amin.

Ko jẹ iroyin mọ pe, gẹgẹ bi orilẹ-ede, a ti wọnu awọn ọsẹ idibo. Awọn eniyan kaakiri orilẹ-ede yi yoo si bẹrẹ si ni jade lọ lati lọ di ibo wọn fun awọn oludije ti o ba wu wọn. Bi o tilẹ wa jẹ wipe ko ki i ṣe iṣẹ mi ni lati sọ ẹni ti o yẹ ki o dibo fun tabi ti ko yẹ ki o dibo fun lara awọn oludije ti o wa nilẹ han ọ, iṣẹ mi ni lati sọ fun ọ pe ki o ma ṣe fi igbẹkẹle rẹ sinu ọkankan ninu wọn ṣugbọn sinu Ọlọrun.

Lotitọ, o jẹ dandan ki o ni idi ti o ṣẹ fẹ fi ibo rẹ gbe ẹni ti o fẹ fi gbe wọle wọle. Amọ, bi o ti wu ki idi ti o ṣe mu eni yi suwọn ati dangajia to, ma ṣe fi igbẹkẹle rẹ sinu ẹni naa ayafi sinu Ọlọrun. Ki si ni idi ti ko ṣe yẹ ki o fi igbẹkẹle rẹ sinu wọn? Idi naa ni pe bi ẹni naa tilẹ jẹ oludije ti Ọlọrun funrarẹ yan, o ṣi le kuna.

Eyi, o wa ṣeni lanu, ni ko ye ọpọ awọn adari ijọ wa ti o n sọtẹlẹ ati ti o n sọ oniruuru ọrọ nipa awọn kan ti wọn gbagbọ pe Ọlọrun ti yan lati jẹ adari fun orilẹ-ede wa ati awọn ipinlẹ wa. Eyi ko si ye wọn nitoripe wọn ko ma kiyesi ọrọ Iwe mimọ. Iwe mimọ fi han wa pe bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun ni o ya eniyan si ipo adari, ko tunmọ si pe yoo ṣe daradara tabi pe yoo jẹ alabukun fun awọn eniyan rẹ. O ṣeeṣe ki o pada jẹ egun fun wọn ati idojuti fun Ọlọrun.

Fun apẹrẹ, a sọ fun wa ninu bibeli pe Ọlọrun ni o yan Sọọlu, ọmọ Kiṣi, ti O si tun ta ororo le lori gẹgẹ bi ọba akọkọ fun Isiraẹli. Ṣe o wa ṣe daradara bi? Rara o, ko ṣe daradara. Nitorina, ni igba ti o to asiko kan, ọrọ rẹ su Ọlọrun. Iwọ naa wo nkan ti a sọ ninu bibeli lori eyi: “Nigba naa ni ọrọ Ọlọwa tọ Samuẹli wa pe, “Emi kaanu gigigidi pe mo fi Sọọlu jọba, nitori pe o ti yipada kuro lẹyin mi, ko si pa ọrọ mi mọ.” Inu Samuẹli si bajẹ gidigidi, o si kepe Oluwa ni gbogbo oru naa.” (1Samuẹli 15:10-11) Njẹ o ri bayẹn? Bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun funrarẹ ni o yan Sọọlu, ti O si tun de ni ade gẹgẹ bi Ọba, O pada kabamọ pe Oun yan an.

Wayi o, awọn eniyan a ma sọ ni ọpọ igba pe Ọlọrun ko ki i kabamọ lori ohunkohun. Amọ ero tara wọn lasan ni eyi, o si lodi si nkan ti o wa ninu iwe minọ. Bi a ti ṣe ri ninu Iwe mimọ, awọn asiko kan wa ti Ọlọrun kabamọ pe Oun ṣe awọn nkankan. Ko si wa pa irọ fun ara rẹ ni awọn asiko yi. Dipo bẹẹ, nṣe ni O dojukọ eyi ti o jẹ ododo nipa awọn nkan naa ti o mu abamọ wa fun un, ti O si mojuto wọn. Nitorina, ti iwọ naa ba n ni ero abamọ tabi ijakulẹ lori awọn igbesẹ kan ti o gbe sẹyin, awọn igbesẹ ti o dabi ẹni pe o dara ni akoko naa ṣugbọn ti o ti wa yipada si eyi ti ko suwọn, ma ṣe gbogun ti ara rẹ pupọju. Dipo eyi, nṣe ni o ko gbajumọ eyi ti o jẹ okodoro ọrọ lori nkan ti o ṣẹlẹ, ki o si ṣe nkan ti o tọ nipa rẹ.

Ọlọrun nilo lati dojuko nkan ti o jẹ otitọ lori ọrọ Sọọlu ati lati ṣe ohun ti o yẹ lori rẹ. O nilo lati ta ororo le elomiran lori dipo rẹ, bi o tilẹ jẹ wipe o ṣi wa lori itẹ. Ṣe inu rẹ wa dun pe Oun ni lati ṣe eyi? Rara! Bawo wa ni ti Wolii Samuẹli ti o ṣoju fun Ọlọrun lati fi Sọọlu jọba? Ṣe inu tirẹ dun si bi ọkunrin ṣe ṣina, ti a ko si le mu wa si ironupiwada? Rara! Dipo bẹẹ, a jẹ ki o ye wa ninu bibeli pe nṣe ni o n ṣọfọ lori Sọọlu titi Ọlọrun fi da a lẹkun rẹ, ti O si sọ fun pe ki o lọ ya elomiran sọtọ dipo rẹ.

Kini koko ọrọ mi? Oun naa ni pe bi o tilẹ jẹ wipe awọn eni iyasọtọ Ọlọrun ni o dibo fun ninu awọn eto idibo ti o n bọ yi, o ko le fi ọwọ rẹ sọya pe wọn ko ni ja ọ kulẹ, nitori wọn le ja ati Ọlọrun ati iwọ kulẹ. Ti ẹni iyasọtọ Ọlọrun ba wa ja wa ku lẹ, ṣe a wa le fọwọ sọya pe awọn ayanfẹ tiwa ko ni ja wa kulẹ? A ko le ṣe bẹ. Ti wọn ba wa ja wa kulẹ, ki ni a fẹ ṣe? Ṣe awa naa yoo wa ma ṣọfọ bi Samuẹli titi di akoko idibo miran ni bi, iyẹn lẹyin ọdun mẹrin si asiko yi?

Adura mi ni pe ko ni si ọkankan ninu awọn ti yoo di adari wa ninu eto idibo yi ti yoo pada wa jẹ ki a ṣọfọ ni orilẹ-ede yi. Ṣugbọn a gbọdọ kiyesara lati ma fi igbẹkẹle wa sinu ẹnikankan ninu wọn ayafi sinu Ọlọrun. Nipa ṣiṣe bayi, bi wọn ba tilẹ ja wa kulẹ, a o le gbojule Ọlọrun lati yi ikuna wọn pada si rere fun wa.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Tí ààyò Ọlọ́run bá le kùnà | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èrèlé 19, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 42 Read More »

Üyelik Bonusu, Erişim, Oyunla

Üyelik Bonusu, Erişim, Oyunlar

Pin Upwards Casino Oyna Türkiye, Pinup’un Resmi Web Sitesi

Oyunları etkinleştirmenin bu ücretsiz yolu, SMS olmadan ve çevrimiçi kulüpte kayıt olmadan tüm misafirler tarafından kullanılabilir. PinUp’ta popüler sosyal ağlarda ve mesajlaşma programlarında açık kişisel sayfalar aracılığıyla kayıt vardır. Örneğin, konuklar VK, Myspace veya Google hesapları aracılığıyla bir hesabı etkinleştirebilecekler. Yani, gün boyunca tüm kazancınızı” “kartınıza veya hesabınıza alırsınız. Pinup, Visa, MasterCard, UnionPay, Troy ödeme sistemlerini destekler. Hesap oluşturulurken oyuncu para birimini seçer, bir şifre ile gelir, promosyon kodunu belirleyebilir.

  • 🌺 Pın Upward operatörü Curaçao’nun lisansı altında çalışır empieza bu adanın yargı yetkisine tabidir.
  • Pinup Casino, lisanslı bir hizmet sunar empieza az yatırımla bile cömert bonuslar empieza kapsamlı oyun seçenekleriyle öne çıkar.
  • Bu mesajlar sayesinde oyuncu tüm yeni bonusların, promosyonların, turnuvaların farkında olacaktır.
  • Kumarhanenin mobil versiyonu, dextop versiyonuna kıyasla biraz basitleştirilmiştir, ancak ana sitenin tüm ana özelliklerini ve avantajlarını korur.

Ayrıca günde oluşturulan başvuru sayısında bir sınır vardır, 3’ü aşarsa beklemeniz veya bir komisyon ödemeniz gerekecektir. Burada sanal takımlar oynar ve sonuç sadece 2-3 dakika içinde öğrenilebilir. Takımların özellikleri ve güçlü/zayıf yönleri vardır ve kimin kazanacağına rastgele bir sayı üreteci karar verir, “hile” hariç tutulur. Para çekme işlemi, belirtilen tüm yöntemlerle ve aynı maksimum limitler dahilinde gerçekleştirilebilir. Talep edilebilecek minimum para çekme tutarı 30 AZN’dir. 🐝 Türkiye’den oyuncular için Pin-up, Android işletim sistemine sahip evrensel bir istemci programı sunuyor.

Pin Up Casino’nun Mobil Versiyonu

Oyuncunun her yetkilendirme prosedüründe bir kullanıcı adı ve şifre girmesi gerekmeyecektir. Hediyenin” “kalitesi sadakat sistemindeki ilerlemeden etkilenir. Durum sisteminde bir oyuncu eine kadar yüksek olursa, kişisel tatil arifesinde o kadar çok şey alır.

PinUp kumarhanesine kaydolmak için önce resmi web siteye gitmeniz, uygun alanı bulmanız ve icat edilmiş şifre ile birlikte e-postanızı oraya girmeniz gerekir. Ayrıca, bir fiziksel IP adresinden veya oyun kulübündeki aile başına birden fazla hesabı etkinleştirmek de yasaktır. Aynı bilgisayar veya mobil cihaz üzerinden Pin Up Casino’da farklı hesaplara (farklı kişilere kayıtlı) giriş yapmak yasaktır. Bu tür giriş denemeleri Pin Up güvenliği tarafından tespit edilecek empieza bu tür kişisel hesapların engellenmesine yol açacaktır. Para yatırma para birimini belirleyen oyuncu, rahat ödeme araçları aracılığıyla casino Pin Up’tan para yatırma ve çekme olasılığını dikkate almalıdır http://innovativeschooldistrict.org/pin-up-app/.

Casino Slotları

Bu yönteme ek olarak, kumarhaneye sosyal ağlardan biri aracılığıyla weil girebilirsiniz. Belirli görevleri yerine getirerek empieza aktivite göstererek elde edilebilir. Örneğin, hesabı doğrulayabilir, profilinizi doldurabilir, 5 slot makinesinde bahis yapabilirsiniz ve daha fazlasını yapabilirsiniz. Sonrasında bu para birimi, diğer ödüllerle takas edilebilir.

Oyuncuların Pinup kumar kulübündeki ödüllerin geri çekilmesi hakkındaki yorumlarının çoğuna göre, kumarhane operatörünün kazanılan parayı ödemesi garanti edilmektedir. Bir ödeme için başvurduktan sonra, fonlar en geç twenty-four saat içinde kullanıcının hesabına yatırılır. Genellikle, doğrulanmış oyuncular için para çekme işlemi anında gerçekleşir. Online casino” “ödeme talepleriyle aşırı yüklenirse transferlerde gecikmeler meydana gelebilir.

Mobil Proqramımı Necə Yeniləyə Bilərəm?

Pin Up desteğine e-posta, canlı sohbet, Vkontakte sosyal ağı empieza Telegram messenger aracılığıyla ulaşabilirsiniz. Para çekme işlemi yalnızca doğrulamadan sonra yapılabilir. Para birimleri arasında ruble, dolar, euro, grivnası, Kazakistan tengesi, Türk lirası ve bir dizi başka para birimi bulunmaktadır.

Pin Up ta Keno ve Fortunate 6 gibi loto oyunları, oyuncuların sayıları seçtiği ve çekilişi beklediği ilgi çekici bir konsept sunar. Oyuncunun görevi, kazancını almak için sanal kartını sayılarla doldurmaktır. The Balloon oyunu SmartSoft Gaming tarafından geliştirilmiş ve sunulmuştur ve � RTP oranına sahiptir. Önceki oyunların aksine, bu oyunun konsepti biraz farklıdır.

Pınup Casino’da Nasıl Oynanır

Erişiminizi kaybettiyseniz, web site üzerinden erişimi yeniden sağlayabileceğinizi unutmayın. Bunu yapmak için giriş yapmayı denediğinizde «Şifremi Unuttum» seçeneğine tıklayın ve erişiminizi posta yoluyla yeniden kazanın. Ayrıca, şirket müşterilerin belgelerini kontrol eder ve yalnızca 18 yaşından büyük olanların kaydolmasına izin verir. Bu, sitede güvenli bir ortamı korumaya ve reşit olmayanlarda kumar bağımlılığını önlemeye yardımcı olur. Bu tür yaklaşımlar, markayı kumarbazlar arasında popüler hale getirmiştir.

  • Doğrulama olmadan, fonların çekilmesinde uzun gecikmeler olabilir, genellikle yeni kullanıcılar için 24 saate kadar.
  • Portalın uluslararası düzenleyici Curacao’dan izni bulunmaktadır.
  • Bu, çoğunlukla klasik yapıya sahip yuvaların dahil olduğu en üst düzey bir seçimdir.
  • Kazançları komisyonsuz almak için, ilk depozitoyu en az 3 kez kaydırmanız gerekir.

Bir oyuncu şifresini unutursa, “Kayıt” menüsünde kişisel hesaba erişimi geri yüklemeye yardımcı olacak özel bir “Şifremi Unuttum” sekmesi vardır. Para yatırma işlemini etkinleştirmek için uygun bonusa (varsa) tıklayın, ardından operatör hesabınıza kredi verecektir. Pin Up on the internet casino’da müşteriler, verilerinin güvenliğini düşünmeden empieza oyundan uzaklaşmadan çok sayıda kaliteli hizmet alırlar. Saytın durante alt kısmında, kullanıcılar için önemli bilgilere linkler bulunur. Pin Up Az resmi saytı, qanunvericiliğe uyğun olaraq kazino bölümüne doğrudan bağlantı vermir.

Pinup Kazino Mobil Proqramı

Bu seçimlerdeki makinelerin seçimi, child zamanlarda slotların durante çok talep edildiğini takip eden kumarhanede ayrı bir ekip kurdu. En yüksek ödemeye sahip makinelerin bir listesini ve buna bağlı olarak kazanma şansının yüksek olduğu özel bir sekmeye gidebilirsiniz. Böylece, bu platformun size g?re olup olmadığını ve tüm tercihlerinize uyup uymadığını belirleyebilirsiniz. Dürüst ve güvenilir bir bahis platformu seçmek, şans oyunlarına başarılı bir başlangıç için en önemli bir adımdır. Pin Upward ile” “oyunun ve gerçek kazançların tadını çıkarabileceksiniz.

  • Doğrudan ana sayfadan indirilir ve Android os veya iPhone’unuza yüklenir.
  • Çoğunlukla, Pin Up Casino uzun süredir belirli bir adreste faaliyet göstermektedir.
  • Bu, yüksek bir bahisle veya aynı zamanda benzersiz hale gelen çift bahis mekaniği pahasına yapılabilir.
  • Her oyuncunun kişisel bilgilerinin Pinup online casino tarafından korunacağı garanti edilir.
  • PvP etkinliklerinde bireysel oyunculara mı yoksa takım etkinliklerine una bahis oynayacağınızı seçin.
  • Bugün, üreticilerin büyük bir kısmı esas olarak yüksek oynaklığa sahip yuvalar üretmektedir.

Kayıtlı oyuncular kapalı sitedeki çeşitli hizmetlerden w tamtym miejscu olarak yararlanabilirler. Ziyaretçiler, takma adlarını ve şifrelerini kullanarak Pin Up kişisel hesabına ve başka bir cihazla serbestçe giriş yapabilirler. Çarpışma oyunu Aviator, çok sayıda stratejiyi uygulamanıza izin verir.

Pin Upward Kulübü Hakkında Genel Bilgiler

Bir kullanıcı kazandığında, hemen parasını şimdi almak ister. Bir banka kartı, e-cüzdan, kripto para birimi kullanabilirsiniz. Bu olursa, ana kaynağın gerçek bir aynasını bulmanız gerekir.

Bu bonusu çevirmek için, alındıktan sonra 7 gün süreniz olacak. Bu süre zarfında, elde edilen parayı oyunlarda kullanmanız gerekecek. Bundan sonra, kişisel hesabınızda, kullanılabilir yöntemlerle kazancınızı çekme seçeneği belirecektir. PinUp indir oyuncuları, kayıt olduktan ve bakiyeyi yükselttikten sonra 2500 TRY’ye kadar alabilir.

⚽️bahis Şirketinin Ofisinde Bir Profil Kaydetme Pin-up Bet

Bonusu etkinleştirmek için kişisel dolabınıza girin ve etkinleştirme düğmesine tıklayın. Pin Up Online casino, kumar pazarında büyük başarılar sahip olan birkaç kişiden biridir. Bütün bunlar, sadece yönetimin çalışmaları değil, aynı zamanda oyuncuların objektif incelemeleri sayesinde. Sonuçta, bir kişi belirli bir çevrimiçi kumarhaneye kaydolmaya karar verdiyse, seçimini kesinlikle bazı bilgilere odaklaması gerekir. Kaynağı, hizmet kalitesini, ödeme hızını, gelişmiş bonus programını ve kulübün diğer cazibelerini daha önce denemiş olan kullanıcıların yorumları olabilir.

  • Şirket, hizmetlerinin dürüstlüğünü garanti ederek yasal bir şekilde faaliyet göstermektedir.
  • Oyuncular, kumar hizmetiyle ilgili incelemelerinde ve yorumlarında, aynanın uzun süredir düzgün çalıştığını söylüyorlar.
  • Farklı ülkelerde oynayan kulüp müşterileri, çok çeşitli konulara ve geniş bir oran yelpazesine sahip çok çeşitli slot makinelerine erişebilecekler.
  • Bu tür yaklaşımlar, markayı kumarbazlar arasında popüler hale getirmiştir.

Pin-Up 950 web sitesine akıllı telefondan girmenin başka bir yolu weil tarayıcı tabanlı mobil sürümdür. Avantajları, kompaktlık, minimum trafik yükü ve masaüstü sürümüne benzer işlevselliktir. Resmi web sitesini, mobil versiyonu ve Pin-up aynasını ziyaret etmeyi teklif ediyoruz. Resmi portala erişim bir nedenden dolayı engellenirse, ikincisine ihtiyaç duyulabilir. Kullanıcı platforma nasıl girerse girsin, kullanıcı dostu arayüz, çok dillilik, kayıt kolaylığı ve daha birçok olumlu yönden memnun kalacaktır.

Pin Up 360 Arizona Üstünlükləri

Oyunculara yerel çekim ve depozito sistemleri mevcuttur. Şirket, hizmetlerinin dürüstlüğünü garanti ederek yasal bir şekilde faaliyet göstermektedir. Pin-UP Casino’da, oyuncuların cüzdanlarını büyük paralarla doldurmaları için farklı yollar vardır. Bunlar arasında kulüp içinde düzenlenen, büyük ve küçük nakit ödüllü turnuvalar yer almaktadır. Pin Up in On line casino turnuvalarının en güzel yanı, hesap durumlarına bakılmaksızın tüm oyunculara açık olmasıdır.

Bunlar çarpışma oyunları, slotlar, canlı bayilerle lobiler, spor bahisleri ve çekilişlerdir. Bu oyunlar oyunculara klasik çevrimiçi online casino oyununu farklı tarzlarda ve benzersiz özelliklerle deneyimleme fırsatı sunar. PınUp TV oyunları kategorisi Boks, Futbol Grid, Dart empieza daha fazlası gibi heyecan verici spor simülasyonlarını içerir.

Yeni Oyunçular Üçün Pin Up Kazino Bonusları Nədir?

Kurulum tablette veya akıllı telefonlarda gerçekleştirilir. Uygulamayı indirmek kullanıcıya çok sayıda fayda sağlar. Bu mesajlar sayesinde oyuncu tüm yeni bonusların, promosyonların, turnuvaların farkında olacaktır.

  • Operatör ayrıca spor etkinliklerine ve medya etkinliklerine bahis kaydetmeyi teklif ediyor.
  • Legalli Pin-Up Casino, Türkiye’den oyunculara hızlı bir kayıt imkanı ve hoşgeldin bonusu alma fırsatı sunuyor.
  • Sonuçta, bir kişi belirli bir çevrimiçi kumarhaneye kaydolmaya karar verdiyse, seçimini kesinlikle bazı bilgilere odaklaması gerekir.
  • Bonusu, önemli tarihten sonraki yedi gün içinde kullanabilirsiniz.
  • Ayrıca günde oluşturulan başvuru sayısında bir sınır vardır, 3’ü aşarsa beklemeniz veya bir komisyon ödemeniz gerekecektir.

Pinup Online Casino’da başlangıç bonusu the girl acemiye verilir. Bununla birlikte, kullanıcı biraz daha fazla harcarsa, serbest dönüşleri para etkinleştirebilir. Pinup, Türk oyuncular için sobre dahil olmak üzere ayrı bir slot machine game seçimi sunuyor. Bunlar arayüzü Türkçeye çevrilmiş, öğrenmeyi ve test out etmeyi kolaylaştıran oyunlardır. Oyuncuya hem sohbet hem de e-posta yoluyla Türkçe olarak cevap verilecektir. Soru derhal ve projenin gerçek bir çalışanının katılımıyla çözülür.

Android Işletim Sisteminde Casino Pin-up Mobil Nasıl Indirilir?

Fakat bonuslar aktif blooming geldiğinde ana hesabınızdaki bakiyeyi çekme hakkınız olmaz. Yalnızca bahis yapılan ve kazanç” “elde edilen tutarı çekebilirsiniz. Bonusları etkinleştirmeye karar vermeden önce dikkatlice düşünmelisiniz.

Ücretsiz oyun çok ilginç ve yoğun ve en önemlisi — tamamen güvenli olduğunu kanıtlayacaktır. Yeni başlayanların pra yatırmak için zorunlu doğrulamadan geçmesi gerekmez. Ziyaretçi hemen ödül kaydırmaları için oynamaya başlayabilir. Ancak kullanıcılar bu bonusu ödül hesabından ödeyebilir ve bu da bütçedeki yükü azaltır. Operatör, Curaçao lisansı altında çalışmakta ve 2016 yılından beri faaliyet göstermektedir. Bugün, Pinap her türlü kumar eğlencesini bir araya getiriyor.

Pin Up Casino Xoş Gəlmisiniz Bonusu

Pin Up’ta, dürüst, güvenilir ve daha da önemlisi kazanılan paranın anında ödenmesi garantisi ile yüksek kalitede heyecan verici oyunlara erişebileceksiniz. Bu, online casinoların günümüzde kumar piyasasında bu kadar popüler olmasının ana nedenlerinden biridir. Farklı ülkelerde oynayan kulüp müşterileri, çok çeşitli konulara empieza geniş bir oran yelpazesine sahip çok çeşitli slot makinelerine erişebilecekler. Ayrıca, Pin-up sitesi kullanıcıları bir bahisçinin ofisinin hizmetlerini kullanabilir ve spor etkinliklerinin sonuçlarına bahis oynayabilir.

Bahis bürosunun avantajı, bunun düşük marjlı bir operatör olması gerçeğidir. Yönetim, her tekliften minimum kar yüzdesini alır ve bu nedenle oranları kesmez. Bütün bunlar, minimum bütçeyle büyük kazançlar elde etmenizi sağlar. Her müşteri için organizatörler bir karşılama paketi sunar ve düzenli promosyonlar neredeyse her yedi günde bir yenilenir. Bu, Türkiye’de son derece popüler olan ünlü bir kumar internet sitesidir.

Pin Up On Line Casino Slot Makineleri

Yalnızca yetişkin oyuncular kişisel hesaplarını etkinleştirebilir. Böylece Pin Up kaydolabilir empieza oyunlara erişim sağlayabilirsiniz. Kayıttan sonra, depozitlere ve bonuslara erişim açılır.

  • Yani, gün boyunca tüm kazancınızı” “kartınıza veya hesabınıza alırsınız.
  • Pin-Up, sektörde müşteri merkezli bir yaklaşım sergileyerek, güven empieza açıklıkta liderdir.
  • İşlem yaklaşık 10 saniye sürer ve gerçek bir posta kutusuna ve şifresine sahip olmanızı gerektirir.

Oyuncular, bir düğmeye basarak balonu kendileri şişirerek empieza ardından potansiyel kazançlarını talep etmek için serbest bırakarak oyuna aktif olarak katılırlar. JetX Pin Upward crash oyunu SmartSoft Gaming tarafından 2018 yılında geliştirilmiştir empieza basit ancak kullanıcı dostu bir arayüze sahiptir. Sol taraf çarpan geçmişini gösterirken, sağ taraf oyuncu kazançlarını sergiler. Oyun alanı ortadadır empieza bahislerinizi yönetebileceğiniz düğmeler bunun altında yer alır. Ayrıca, Türkiye’den kullanıcılar için özel promosyon kodu mevcut olduğunu hatırlatmak isteriz.

Pin-up Casino İndir – Türkiye

Özel sanal paraların yardımıyla kaybedilen fonlardan para iade etmek mümkündür. Sanal kredilerle kumarbazlar gerçek Türk lirası satın alabilirler. Oyuncunun bir şifre bulması, e-posta ya da kişisel telefon numarası vermesi gerekir. Pin Up ta klasik kart oyunlarından Rulet, Boks, Dart ve daha fazlasına kadar 27 yüksek kaliteli TV oyununu keşfedin. Bu oyun, saygın sağlayıcı Spribe tarafından geliştirildi ve 2019’da ortaya çıktı.

  • Belirli sayıda bahis için, oyuncuya bir piyango bileti açma fırsatı verilir.
  • Kayıtla ilgili sorularınız olursa, the girl zaman çevrimiçi sohbet üzerinden müşteri” “desteğine yardım talebinde bulunabilirsiniz.
  • Bu soru genellikle Türkiye’deki acemi kumarbazlar tarafından sorulmaktadır.
  • Bu tür yinelenen kişisel hesaplar (çoklu hesaplar) tespit edilirse, hepsi kapatılacak empieza para yatırma hesapları iptal edilecektir.

Ayrıca, sektördeki en iyi yenilikleri sunan Türkiye’de Pin Up’tır. İkincisi, üst düzey grafiklerle slot oynamak daha kolay ve daha rahat hale gelir. Oyunlar çok daha hızlı yüklenir ve asıl önemli olan bataryayı yüklememeleridir. Ziyaretçinin akıllı telefonunu sürekli olarak şarj cihazına bağlaması gerekmeyecektir.

Pin Upward Casino Azerbaijan-da Pulsuz Kazino Oyunları Oynaya Bilərəmmi?

Pın Up Türkiye online casino web sitesi 35’ten fazla heyecan verici crash oyunu içerir. Bu tür oyunlarda, oyunun ana karakteri üzerine bahis oynarsınız. Bu bir uçak, uzay roketi, jet veya başka herhangi bir şey olabilir. Uçak havada nenni kadar uzun süre kalırsa, katsayı o kadar yüksek olur ve bu da bahsinizin miktarı ile çarpılır. Göreviniz, uçak oyun alanını terk etmeden önce parayı nakite çevirmektir.

  • Bu önemlidir, çünkü birçok kumarhane bonusu ve gerçek bir hesabı “lehimleyerek” birleştirir ve böylece bahis oynanana kadar kazançların çekilmesine izin vermez.
  • Curacao lisansı altında faaliyet gösteren ve müşterilerine yalnızca yüksek kaliteli hizmet sunan uluslararası bir kumar sitesiyiz.
  • Mobil move hizmetleri ile WebMoney ve Yumani kullanırken, maksimum yatırma limiti 1500 AZN olarak belirlenmiştir.
  • Pin Up Club’a katılmak ve parayla oynamaya başlamak için kayıt prosedüründen geçmeniz gerekir.
  • Slot makinelerindeki minimum bahislerin boyutları, oyunların algoritmaları tarafından belirlenir.

Pin Up TR şirketi, cömert bonusları ve geniş oyun koleksiyonu sunan bir kumarhane sektörü lideridir. Ayrıca, alternatif bir oyun deneyimi için mobil uygulamadan da faydalanabilirsiniz. Depozitler, banka kartları veya elektronik ödemelerle yapılabilir. Sorularınız” “olursa, müşteri desteğine the woman zaman başvurabilirsiniz. Pin Up online sitesine kayıt olduktan sonra, depozito yatırma imkanına erişim açılır. Bonusları çevirdikten veya oyunlardan kazanç sağladıktan sonra, para çekmeyi düşünebilirsiniz.

Üyelik Bonusu, Erişim, Oyunla Read More »

Fi ojú sílẹ̀ láti ṣọ́ wọn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èrèlé 12, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 41

Olufẹ: ki oore ọfẹ ati aanu di pupọ si fun ọ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Èrèlé 2023. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun tikararẹ ṣe ọ ni mimọ ati ailabuku, lọkan, lẹmi ati lara, nigba ti Jesu Oluwa ati Olugbala wa ba de. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu iwe mimọ, Jesu Kirisiti Oluwa wa n pada bọ wa fun ijọ rẹ ni akoko ti Ọlọrun Baba ti yan. Ṣugbọn ko ki i ṣe ijọ eleeri tabi ijọ ti o ti dibajẹ ni O n pada bọ wa fun. Dipo eyi, O n pada bọ wa fun ijọ ti ko ni abuku, ti ko ni abawọn ati eyi ti yo wa ni ibarẹ pẹlu rẹ nigba ti o ba de. (Wo: Efesu 5:26; 2Peteru 3:14)

Amọ ṣe a wa le wa ni ailabawọn, ailabuku ati aini ohunkohun ti le fa idojuti nigba ti O ba pada wa? Bẹẹni, a le e wa bẹ ẹ. A le e wa bẹ ẹ nitoripe Ẹmi Ọlọrun wa ninu wa, O si n fi gbogbo ara ṣiṣẹ lati ri pe eyi ri bẹ. Bẹẹni, O n ṣiṣẹ ni gbogbo igba lati ri daju pe iṣẹ rere ti O bẹrẹ ninu wa nigba ti a ṣẹṣẹ di atunbi jẹ ṣiṣe titi di ọjọ Oluwa. Nitorina, wiwa ni ailabuku wa nigba ti Jesu ba de ko da lori ifẹ wa tabi ilakaka wa ṣugbọn o da lori iṣẹ Ẹmi Ọlọrun ninu wa ati lori wa. (Wo: Filipi 1:6 & 2:12-13)

Amo ṣa o, awa naa si wa tun gbọdọ ni lọkan lati wa ni ailabaku nigba ti O ba pada de. Yatọ si iyẹn, a tun gbọdọ ma ṣe amulo oore-ọfẹ rẹ lati gbe igbe aye ti O fẹ ki a gbe. Aijẹbẹ, o ṣeeṣe ki o jẹ wipe awa gan ni a o papa wa fooro iṣẹ ti O n ṣe lati jẹ ki a wa ni alailabuku.
Siwaju si, o ṣe pataki ki a ma fi oju silẹ lati ṣọ ara wa, ki Satani ma ba ṣe aṣeyọri ni titan ẹnikẹni kuro laarin wa lọ si ibi ti yoo ti pa igbagbọ ati aye wọn run. Bibeli sọ awọn nkan wọnyin fun wa lori ọrọ yi:

“Ẹ kiye sara, ara, ki ẹnikẹni ninu yin ki o ma ṣe ni ọkan buburu ati ti aigbagbọ, eyi ti yoo mu yin kuro lọdọ Ọlọrun alaiye.” (Heberu 3:12)

“Ẹ maa kiye sara ki ẹnikẹni ki o ma ṣe kuna oore-ọfẹ Ọlọrun, ki gbongbo ikoro kan ki o ma baa hu soke ki o si yọ yin lẹnu, ọpọlọpọ a ti ipa rẹ di aimọ. Ki ẹnikẹni ma baa di alagbere tabi alaiwa-bi-Ọlọrun bi Isọ, ẹni ti o ti itori okele ounjẹ kan ta ogun ibi rẹ. Nitori ẹyin mọ pe lẹyin naa, nigba ti o fẹ lati jogun ibukun naa, a kọ ọ (nitori ko ri aaye ironupiwada) bi o tilẹ jẹ wi pe o fi omije wa a gidigidi.” (Heberu 12:15-17)

Njẹ o ri bayẹn? Ti gbogbo wa ba fẹ wa ni mimọ ati ailabuku nigba ti Jesu Oluwa wa ba pada de, a gbọdọ fi oju silẹ lati ma ṣọ ara wa. Nipa ṣiṣe eyi, a o le gbe igbesẹ akin lati tọ ara wa sọna, lati ba ara wa wi ati lati daabo bo awọn ara wa, ti a ba kẹfin pe Satani n ṣiṣẹ lati fi pakute mu wọn nipasẹ owu jijẹ, ojukokoro, ẹtanu, iṣọtẹ, ainitẹlọrun, pansaga tabi iṣẹ ẹran ara miran.

Fun apẹrẹ, nigba ti awọn ara ile Kloe ti ijọ awọn ara Kọrinti ri pe ẹran ara ti gba ijọba ijọ yi, wọn ko fi akoko ṣofo rara lati fi to Apọsiteli Pọọlu, ti o jẹ adari wọn ninu ẹmi, leti. Wọn ri wipe iyapa, owu jijẹ, igberaga, iṣekuṣe, iyanjẹ ati aibikita fun igbagbọ awọn ti wọn ṣi jẹ ọmọ ọwọ ninu igbagbọ ti n fa ijọ yi ya. Nitori eyi wọn kọ lẹta si apọsiteli yi, wọn si bere fun amojuto rẹ ni kiakia. Idi niyi ti o ṣe kọ 1Kọrinti. Nitorina, lẹta yi jẹ idahun si ipohunrere ati adura awọn ọmọ ijọ kan ti wọn fẹ ri pe ijọ Ọlọrun wa ni mimọ ati ni ailabuku nigba ti Jesu ba de.

O wa ṣeni laanu pe, loni, ti awọn ara kan ba n ṣe nkan ti o jọ mọ eyi, ti wọn bẹrẹ si ni gbe igbesẹ lati ri wipe ijọ wọn wa ni yiya si mimọ si Oluwa, nṣe ni awọn ara miran yoo ma pe wọn ni orukọ, ti wọn yoo si ma ba wọn ja. Ki ni idi? Idi ni pe ifẹ wọn si okunkun si wa digbi. Nitorina, wọn ko fẹ ki iṣẹ rẹ di fifihan tabi mimojuto. Ti a ba wa fi aye gba irufẹ awọn wọnyi lati pa otitọ lẹnu mọ tabi tẹ ori rẹ ba laarin wa, nṣe ni a o ma ran wọn lọwọ lati pa ara wọn ati awọn miran run ati lati ba orukọ Ọlọrun jẹ.

Nitorina, ti wiwa wa ni ailabuku nigba ti Jesu ba de ba ka ọ lara, fi oju rẹ silẹ, ki i si ṣe lati ṣọ ara rẹ nikan ṣugbọn lati ṣọ awọn ara rẹ yoku naa. Ti o ba si wa ri wipe wọn n kuna ni ọna kan tabi omiran, ma ṣe fa ṣẹyin rara lati koju wọn tabi awọn ti o le ran wọn lọwọ pẹlu otitọ, yala inu wọn dun si tabi ko dun si. Amọ ọjọ kan n bọ ti wọn yoo dupẹ lọwọ rẹ fun ṣiṣe oun ti o tọna lati gba wọn la tabi ti wọn yoo da ara wọn lẹbi fun kikọ ifẹ Ọlọrun fun aye wọn silẹ.

Ki o ni ọṣẹ ti o ga.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Fi ojú sílẹ̀ láti ṣọ́ wọn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èrèlé 12, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 41 Read More »

Ọ̀nà láti jẹ́ pípamọ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èrèlé 05, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 40

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu oṣu Èrèlé 2023. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun pa ọ mọ kuro ninu gbogbo ibi awọn ọjọ ikẹyin yi ti o n pa igbagbọ ati aye awọn eniyan run. Amin.

Mo gba adura yi si Ọlọrun fun ọ nitoripe mo mọ pe ifẹ rẹ ni lati pa gbogbo awa ti a jẹ ọmọ rẹ mọ kuro ninu idibajẹ ati awọn ibi ti o wa ninu awọ ọjọ ikẹyin yi. Bibeli tilẹ sọ fun wa pe a le gbẹkẹle lati pa wọn mọ nitori olododo Ọlọrun ni o jẹ (1Tẹsalóníkà 5:23-24). Ṣugbọn ọtọ ni ki Ọlọrun mura giri lati pa aye ati igbagbọ wa mọ; ọtọ tun si ni ki awa naa fi ara wa si ibi ti yoo ti le ṣe bẹ ẹ. Ti o ko ba fi ara rẹ si ibi ti Ọlọrun ti le pa aye ati igbagbọ rẹ mọ, o ko le wa ni ipamọ. Eyi ko si ki ṣe epe. Otitọ pọnbele ni.

Bawo wa ni o ṣe le fi ara rẹ si ibi ti Ọlọrun ti le pa ọ mọ kuro ninu awọn idibajẹ awọn ọjọ ikẹyin yi? O le ṣe eyi nipa fifi ara rẹ jin fun ọrọ otitọ rẹ, yala o rọrun fun ọ lati tẹwọgba tabi ko rọrun fun ọ lati tẹwọgba. Pọọlu, ninu lẹta rẹ si Timoti, sọ eyi:

“Nitori naa mo paṣẹ fun ọ niwaju Ọlọrun, ati Kirisiti Jesu, ẹni ti yoo ṣe idajọ alaaye ati oku, ati nitori ifarahan rẹ ati ijọba rẹ. Waasu ọrọ naa, ṣe aisinmi ni akoko ti o wọ, ati akoko ti ko wọ; baniwi, ṣe itọni, gbani niyanju pẹlu ipamọra ati ẹkọ gbogbo. Nitori pe igba yoo de, ti wọn ki yoo le gba ẹkọ ti o ye kooro, ṣugbọn bi wọn ti jẹ ẹni ti eti n rin, wọn o lọ ko olukọ jọ fun ara wọn ninu ifẹkufẹ ara wọn. Wọn o si yi eti wọn pada kuro ninu otitọ, wọn o si yipada si itan asan.” (2Tìmótíù 4:1-4)

Ki ni Pọọlu sọ fun Timoti ninu akọsilẹ yi? Akọkọ, o sọ fun pe ki o ma waasu ọrọ Ọlọrun dipo ti yoo fi ma fi ero ọkan tirẹ, ero ọkan awọn eniyan ti o gbaju-gbaja lawujọ, itan adugbo tabi iṣeṣe ṣe iwaasu. Ekeji, o sọ fun pe ki o ma wa ni igbaradi lati tọ awọn ọmọ Ọlọrun sọna, lati ba wọn wi ati lati gba wọn niyanju, yala o rọrun fun tabi ko rọrun fun. Ṣugbọn ṣe ko yẹ ki Timoti ti mọ awọn nkan wọnyi tẹlẹ ni, paapaa julọ niwọn igba ti o jẹ wipe pasitọ awọn pasitọ ni o jẹ? O yẹ ki o ti mọ wọn.

Ki wa lo de ti o fi nilo ẹnikan lati ṣeṣẹ ma pasẹ fun lati fi ara rẹ jin fun ṣiṣe awọn nkan wọnyi? Bi a ti ri ninu akọsilẹ yi, idi ni pe akoko kan n bọ (akoko naa si ti de bayi) ti ọpọ awọn ti o pe ara wọn ni onigbagbọ ninu Kirisiti Jesu ko ni fi ara mọ ẹkọ ti o ye kooro ṣugbọn ti wọn yoo wa awọn ti yoo ma sọ nkan ti eti ti o n rin wọn fẹ gbọ fun wọn. Pọọlu tilẹ tẹsiwaju lati sọ wipe awọn wọnyi yoo yi eti wọn pada kuro lọdọ otitọ ki wọn ba le ma gbọ awọn itan abalaye ati irọ. Nigbati ti eyi ba si ṣẹlẹ, o ṣeeṣe ki Timoti bẹrẹ si ni ro wipe boya oun ti fe le mọ wọn ju, ki o si wa titori eyi bẹrẹ si ni yi iwaasu rẹ pada lati tẹ ifẹ wọn lọrun. Nitorina, Pọọlu kilọ fun niwaju Ọlọrun ati niwaju Jesu Kirisiti lati ma ṣe bẹ ẹ. Aijẹbẹ, yoo pa iṣẹ iranṣẹ rẹ run, yoo si tun padanu ere rẹ.

Nibakanna, ọpọ ninu ijọ loni ni ko fẹ fi ara mọ otitọ mọ, iyẹn ti wọn ba tilẹ ti fi igban kankan tẹlẹ fi ara mọ ọn. Idi si niyi ti wọn fi n gba inu ijọ kan de inu ijọ miran, ti ko si jẹ fi idi mọlẹ si ibi kankan. Awọn adari bi Aarọni ti yoo fun wọn ni ohunkohun ti wọn ba fẹ, bi o tilẹ jẹ ere wura ni, tẹ awọn wọnyi lọrun ju awọn adari ti yoo koju wọn pẹlu otitọ nipa aye wọn ati nipa ifẹ Ọlọrun fun wọn. (Wo: Ẹ́kísódù 32)

Wayi o, otitọ ti o wa nibẹ ni pe Ọlọrun ko le pa irufẹ awọn eniyan bi eyi mọ kuro ninu idibajẹ tabi ko wọn yọ ki eṣu ma ba ṣi wọn lọna tabi pa wọn run. Ti iwọ naa ko ba si fẹ ki opin aye rẹ ri bi ti wọn, ti o ba fẹ ki Ọlọrun ko ọ yọ ni awọn ọjọ ikẹyin yi, ki O si tun jẹ ki igbagbọ rẹ duro deede, nṣe ni ki o ya fi ara rẹ jin fun ọrọ rẹ ti o ye kooro ati fun itọni ti Ẹmi, dipo eyi ti iwọ yoo fi ma wa awọn ti yoo ma fi ọwọ ra ọ lori ti o o fi ṣegbe kiri. Mo si tun fẹ ki o mọ eyi daju: awa kan si wa ti a ko ni yi iwaasu wa pada lati tẹ ọ lọrun. Bẹẹni, awa kan si wa ti a ko jẹ fun ọ ni ere wura kankan lati bọ, ohun yowu ki o sọ nipa wa tabi ki o ro nipa wa. Idi si ni pe iwọ kọ ni a o jiyin fun bikoṣe Ọlọrun ti O ran wa niṣẹ. Njẹ ki Ọlọrun fun ọ ni ọkan ti yoo ma fi igba gbogbo wa ni irẹlẹ lati tẹwọgba ọrọ otitọ rẹ lalai jiyan. Amin.

Kí o ní oṣu Èrèlé 2023 tí ó ga.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ọ̀nà láti jẹ́ pípamọ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èrèlé 05, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 40 Read More »