Kíni ìdí tí a fi fi ipá báalòpọ̀? | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Okúdù 25, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 8
Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o kẹyin oṣu Okudu 2023. Adura mi ni pe ki Ọlọrun ma fi gbogbo igba pa ọ mọ ki ifẹ awọn ọna ti awọn ti aye yi n tọ ma ba gba ọkan rẹ, ki o ma ba ko ara rẹ sinu itiju tabi iparun, ni orukọ Jesu. Amin.
Bi a ti ṣe fi han wa ninu bibeli, igba kan wa ti ọmọ-ọba kan ti a n pe ni Ṣẹkẹmu fi ipa ba Dina, ọmọbinrin Jakọbu, lo pọ. Lẹyin-ọ-rẹyin, eyi si wa jẹ ki awọn ẹgbọn rẹ, Lefi ati Simeoni, jade lati gbẹsan nipa pipa gbogbo ilu ọmọ-ọba yi run. Nitorina, ko ki i ṣe nkan tuntun ni ki awọn eniyan fi ipa ba eniyan lopọ. Ko si ki i ṣe nkan tuntun naa ni ki awọn eniyan gbe gbogbo igbesẹ ti wọn ni agbara lati gbe, eyi ti o le yọri si ki wọn pa gbogbo ẹbi, ilu tabi ẹya kan run, lati gbẹsan ẹṣẹ ẹnikanṣoṣo. Nitorina, ki o to ṣe ika fun ẹnikẹni, ma fi gbogbo igba ranti pe ko ki i ṣe gbogbo eniyan naa ni o ma n fi igbẹsan silẹ fun Ọlọrun. Awọn miran le lọ debi wipe ki wọn fi iya jẹ gbogbo idile rẹ nitori ẹṣẹ rẹ si wọn. (Wo: Jẹnẹsis 34)
Ṣugbọn ṣa, bawo ni Dina ṣe di ẹni ti ọkunrin yi n fi ipa balopọ? Bibeli dahun eyi fun wa nipa sisọ pe, “Dina ọmọbinirin Lia, ti o bi fun Jakọbu si jade lọ lati wo awọn ọmọbinrin ilu naa. Nigba ti Ṣẹkẹmu, ọmọ Hamori, ara Hifi, ọmọ ọba ilu naa ri i, o mu un, o fi ipa baa lo pọ, o si ba a jẹ, o sọ ọ di alaimọ.” (Jẹnẹsisi 34:1-2) A jẹ pe nkan ti o fi aye gba Ṣẹkẹmu lati ri nkan ṣe si Dina ni pe o fi ile baba rẹ silẹ lati lọ bẹ awọn ọmọbinrin ilẹ naa wo. Ti ko ba fi ile baba rẹ silẹ lati lọ da nkan pọ mọ awọn ọmọge ilẹ naa ni, ko ba ma ti lugbadi ifipabanilopọ.
Kini eyi n sọ fun ọ? Ohun naa ni pe o ye ki o mọ irufẹ ibi ti ori rẹ yoo jẹ ki ẹsẹ rẹ gbe ọ lọ. Ko ki i ṣe ibi gbogbo naa ni o wa ni ailewu fun ọ lati lọ. Ko ki i ṣe gbogbo ọrẹ tabi alabajọṣiṣẹpọ naa ni ko si ewu fun ọ lati bẹ wo. Nitorina, ki o to bẹrẹ si ni bẹ awọn eniyan wo tabi ba wọn jade, ri daju pe o mọ bi ibi ti wọn n mu ọ lọ ṣe jẹ ailewu fun ọ si. Ti o ko ba mọ daju pe ibi ti o n lọ ko ni wu ọ ni ewu, iyẹn ti ko ba si nkan miran n bẹ, o yẹ ki o mọ pe lilọ si ibẹ ko to nkan ti o yẹ ki gbẹmi ara rẹ le lori, ti ko ba ki i ṣe iyinrere Jesu ni o n gbe ọ lọ si ibẹ.
Njẹ o tilẹ mọ pe awọn ibi kan wa ti ko yẹ ki o mu iyinrere Jesu lọ, ti ko ba jẹ wipe o gba aṣẹ taara-taara lati ọdọ Oluwa lati ṣe bẹ ẹ? A ri ka ninu iwe mimọ pe Ẹmi Kirisiti kọ fun Apọsiteli Pọọlu ati awọn akẹgbẹ rẹ lati lọ waasu ni awọn ibikan. Kini idi? A ko sọ fun wa. Ṣe o wa le jẹ wipe Ọlọrun ko fẹ ki awọn ti o wa ni awọn ibi wọnyi di ẹni igbala ni? Rara, ko jẹ jẹ bẹẹ. Idi si ni pe bibeli sọ fun wa pe Ọlọrun fẹ ki a gba gbogbo eniyan la. (Wo: Iṣe Apọsiteli 16:6-8; 1Timoti 2:3-4)
Ki lo wa fa, nigbana, ti O fi kọ fun awọn ọkunrin yi lati wọ awọn ibi ti a sọ yi lọ lati waasu iyinrere ninu wọn? O le jẹ wipe o ṣeeṣe ki ewu wu wọn nibẹ ni asiko yi. Nitorina, ki iwọ, gẹgẹ bi ọkunrin, to bẹrẹ si ni mu iyinrere lọ si ọdọ awọn aṣewo ni ile itura wọn, ri daju pe o gbọ daradara lati ẹnu Ọlọrun. Ki iwọ naa pẹlu, gẹgẹ bi obinrin, to bẹrẹ si ni mu iyinrere tọ awọn ẹru-iku igbooro lọ ni abẹtẹ wọn, ri daju pe Ẹmi Ọlọrun ni o n dari rẹ. Aijẹbẹ, o ṣeeṣe ki iwọ naa lugbadi irufẹ nkan ti o ṣe Dina Jakọbu.
Nikukuru, bi a tilẹ ṣe ri ni ti ọrọ Dina, ko jade tọ awọn ọmọbinrin ilu naa lọ nitoripe o fẹ yi wọn pada kuro ninu ibọriṣa sọdọ Ọlọrun. Dipo bẹẹ, o lọ lati ki wọn ni. Eyi tunmọ si pe o ri wọn gẹgẹ bi ọrẹ, o si fẹ wa pẹlu wọn. O tilẹ ṣeeṣe ki o jẹ pe bi o ti ṣe da wa nile ni o su u ni ọjọ ti a n wi yi, ti o si wo pe ki oun kuro ni ile wọn ti ko ni arinrin, ile ti awẹjẹ-wẹmu ko ma lọ nibẹ, ile ti ko si orin taka-sufe lati jo si nibẹ ati ti ko si tun si awọn adẹrin poṣonu nibẹ lati jẹ ki eniyan gbagbe ibanujẹ rẹ. Ṣugbọn nigba ti ilẹ ọjọ yi yoo fi su, o ti wa ye oun gan funrarẹ pe ile wọn ti ko dun yẹn gan ni ibikan ṣoṣo ti ewu ko ti le wu ninu ilu naa.
Loni, a ni ọpọlọpọ Kirisitiẹni, paapaa julọ awọn ti o jẹ obinrin, ti awọn naa, bi Dina Jakọbu, ro wipe ilana ijọba Ọlọrun ko tasánsán to. Nitorina, wọn fẹ tọ diẹ wo lara iṣesi ti awọn ti aye yi. Rara o, awọn ko ṣetan lati rin ni ihoho wọ ọja bi ti wọn tabi lọ si awọn patí alẹ bi ti wọn tabi ko awọn ọrẹkunrin tabi ọrẹbinrin jọ bi ti wọn. Ṣugbọn wọn ṣa a fẹ tọ diẹ wo lara nkan ti wọn n ṣe. Eyi si ma n farahan ninu bi wọn ti ṣe n mura ati ninu iṣesi wọn nigba ti wọn ko ba si ninu awọn ipade ijọ wọn ati nipa ọna ti wọn n gba lo awọn ohun elo ibaraẹni-sọrọ ti ori ẹrọ ayelujara.
Wayi o, ko si ni ki irufẹ awọn eniyan yi, ti a ko ba ṣaanu fun wọn, ma fẹrẹ run aye wọn lọna kan tabi omiran bi Dina Jakọbu. Nigba ti eyi ba si ti wa ri bẹ ẹ tan, ohun gbogbo ti wọn ti n lakaka lati pa mọ ninu aye wọn ni wọn yo padanu laarin iṣẹju aaya. O wa le je wipe itiju ti yoo tẹle eyi gan ni yoo kuku fi idi iparun wọn mulẹ. Nitorina, ki o to gbesẹ rẹ jade kuro ninu aala aṣẹ Ọlọrun fun ọ, má ronú nìkan nipa ohun ti yoo jẹ èrè re nipa ṣiṣe bẹ, ṣugbọn tun ronu nipa ohun ti o o padanu nipa ṣiṣe e. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ma jẹ ki o fi agọ̀ tabi agídí sar lọ si ibikibi ti a o ti pa ọ run. Amin.
Ki o ni ọsẹ alayọ.
Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)



