August 2023

A kò ní pamọ́ kúrò lójú rẹ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal Ọjọ́: Ògún 27, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 17

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o pari oṣu Ogun 2023. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun ri daju ni gbogbo igba pe ohunkohun ti o nilo fun isoriire ati ibalẹ-ọkan rẹ ko jẹ pipamọ fun ọ, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi Luuku ti ṣe kọ ọ silẹ ninu iyinrere rẹ, ọjọ kan wa ti Jesu Oluwa wa sọkun lori ilu Jerusalẹmu, ti O si wipe, “Ibaṣepe iwọ mọ, loni yii, ani iwọ, ohun ti i ṣe ti alaaafia rẹ! Ṣugbọn nisinsin yii wọn pamọ kuro loju rẹ.” (Luùkù 19:42) Ki ni a pamọ fun awọn olugbe Jerusalẹmu, bi Oluwa wa ti fi han nibiyi? Nkan ti wọn nilo fun alaafia wọn!

Nibakana, a ri ọpọ loni ti ohun ti wọn nilo fun ibalẹ-ọkan ati iṣoriire wọn jẹ pipamọ fun wọn. Niwọn igba ti a ba si pamọ fun wọn, wọn ko ni mọ ibalẹ-ọkan tabi iṣoriire. Dipo eyi, nṣe ni wọn yoo kan ma fi asiko, okun ati awọn nkan ini wọn ṣofo nipa wiwa alaafia ati isinmi ni ibi ti wọn ko ti si. Nitorina, ara wọn adura ti o yẹ ki o ma fi igba gbogbo gba laye ni pe ki Ọlọrun ṣi oju rẹ si awọn nkan naa ti o wa fun alaafia ati iṣorire rẹ, ni ibamu pẹlu aini ojoojumọ.

Ki ni o jẹ ki opo Ṣarefati ati ọmọkunrin rẹ la iyan ọdun mẹta ti ilẹ Isiraẹli ni iriri rẹ ni asiko ọba Ahabu kọja? Nkan ti o fa ni pe Ọlọrun ṣi oju rẹ lati ri ohun ti o nilo lati ṣe fun ipamọ wọn. A ko sọ bi Ọlọrun ti ṣe ṣe eyi fun wa. Ṣugbọn a ṣa a ri mọ ninu bibeli pe Ọlọrun di-i-di sọ fun Elija pe Oun ti pasẹ fun opo kan lati tọju rẹ ni asiko iyan naa. Nitoripe obinrin yi si gbe igbesẹ ni ibamu pẹlu nkan ti Ọlọrun ti sọ fun, ohun ati ọmọkunrin rẹ la iyan naa kọja. (Wo: Awọn Ọba 17)

Siwaju si, ki ni o jẹ ki Jabeṣi bọ lọwọ iṣẹ ati igbe aye ikoro ati inira? Nkan ti o fa ni pe a ṣi oju rẹ lọjọkan lati mọ pe ti o ba le gba adura si Ọlọrun lori ọrọ rẹ, nkan yoo yipada fun un. Nigba ti o si gbe igbesẹ igbagbọ, ti o gbadura si Ọlọrun lori ọrọ naa, Ọlọrun da a lohun, O si ṣe ni ọlọla ju gbogbo awọn arakunrin rẹ lọ. (Wo: 1Kiróníkà 4:9-10)

Lafikun, ki ni o fa ti obiinrin onisun ẹjẹ ṣe ri iwosan rẹ gba, lẹyin ti o ti fi ọdun mẹjila gbako wa itusilẹ lori pàbó? Nkan ti o fa ni pe a ṣi oju rẹ lọjọkan lati ri pe ti o ba le wa Jesu Oluwa wa kan, ki o si fi ọwọ kan iṣẹti aṣọ rẹ, ara rẹ yoo ya. Nigba ti o si wa Jesu kan, ti o fi ọwọ kan iṣẹti aṣọ rẹ, lẹsẹkẹsẹ ni a mu larada kuro ninu aisan rẹ. (Wo: Máàkù 5:25-34)

Wayi o, kiyesi pe ninu gbogbo apẹrẹ ti mo ṣẹṣẹ fi silẹ yi, ko si ẹnikẹni ti o sọ fun awọn eniyan yi ohun ti wọn nilo lati ṣe lati ni iriri igbala, iserere tabi iwosan. Ọlọrun funrarẹ ni O fi han ọkan wọn ohun ti wọn gbọdọ ṣe. O si le jẹ pe nkan ti iwọ naa nilo ni eyi. Nkan ti mo n sọ ni pe nkan ti iwọ naa nilo lati ni iriri igbega, iwosan tabi ibalẹ-ọkan ti Ọlọrun ti pese silẹ fun ọ le ma jẹ ohun ti oniwaasu tabi wolii kankan mọ tabi le sọ fun ọ. Dipo bẹẹ, o le jẹ ohun ti Ọlọrun funrarẹ ni lati fi han iwọ alara gangan ni.

Nitorina, gbadura pe ki Ọlọrun ri daju pe ohun gbogbo ti o nilo lati ni iriri ẹkunrẹrẹ didara rẹ ninu aye rẹ ko jẹ pipamọ fun ọ mọ ṣugbọn eyi ti han kedere si ọ. Siwaju si, gbadura pe bi Ọlọrun ba ti n fi ohun ti o nilo lati ṣe fun ilọsiwaju rẹ laye tabi fun ọ lati ni iriri iwosan tabi igbala ninu aye rẹ han ọ, o o tun ni ọgbọn, okun ati igboya ti o peye lati gbe igbesẹ ni ibamu pẹlu nkan ti O ba fi han ọ. Bẹẹ si ni yo ri, ni orukọ Jesu. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

A kò ní pamọ́ kúrò lójú rẹ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal Ọjọ́: Ògún 27, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 17 Read More »

Má lo ìrírí rẹ láti dájọ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ògún 20, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 16

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lailodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran niu oṣu Ògún 2023. Adura mi si ni pe ki ọkan rẹ ma fi gbogbo igba gba okun lati ma fi ohunkohun ropọ ọrọ Ọlọrun ninu aye rẹ, ki o ba le ni iriri gbogbo ete rere Ọlọrun fun aye rẹ. Amin.

Laipẹ yi, bi mo ti ṣe n ka iwe ẹni-ọwọ Ọlọrun kan ni mo sọda si abala kan ti o ti n gbiyanju lati lo iriri rẹ nidi okowo rẹ lati fi idi itunmọ ti o fun awọn nkankan ti a sọ ninu Iwe mimọ nipa sisan idamẹwa ati fifi ọrẹ akọso silẹ mulẹ gẹgẹ bi eyi ti o tọ. Bi o tilẹ wa jẹ wipe ko si nkan ti o buru ninu ki a lo iriri wa laye lati ṣe alaye awọn otitọ bibeli kan tabi omiran, a gbọdọ yago fun aṣiṣe titunmọ ọrọ Ọlọrun pẹlu iriri wa. Ẹni ti O gbọdọ tunmọ nkan ti Iwe mimọ sọ fun wa ni Ẹmi Mimọ. Oun ko si wa jẹ tunmọ Iwe mimọ nipa lilo iriri wa tabi bi nkan ti ṣe ri lara wa. Dipo eyi, nṣe ni yoo fi Iwe mimọ tunmọ Iwe mimọ.

Wayi o, bi a ti ṣe ri ninu Iwe mimọ, Ọlọrun pasẹ fun Mose ati Aarọni nigbakan lati sọrọ si apata ti o wa niwaju awọn ọmọ Isiraẹli ki omi ba le jade lati inu rẹ fun awọn eniyan naa lati mu. Ṣugbọn dipo ki wọn sọrọ si apata naa, nṣe ni Mose la ọpa ọwọ rẹ mọ ọn lẹẹmeji. Ṣe omi wa jade lati inu rẹ tabi ko jade? Omi ma jade lati inu rẹ fun awọn eniyan naa lati mu. Amọ ṣe iyẹn wa jasi pe iriri ti awọn eniyan naa ni ni asiko yẹn jẹ eyi ti o waye nipa ṣiṣe amulo ọrọ Ọlọrun lọna ti o tọna? Rara o! (Numeri 20:1-12)

Mose ati Aarọni ṣe amulo ọrọ Ọlọrun ni ọna ti ko tọna ni asiko yi. Sibẹsibẹ awọn eniyan wọn ni iriri ipese omi lati ọdọ Ọlọrun. Ṣugbọn lati fihan gbogbo eniyan pe Mose ati Aarọni kuna, Ọlọrun sọ fun wọn pe wọn ko ni wọ Ilẹ-ileri. O si ri bẹ ẹ. Nitorina, o ṣeeṣe ki o lo ọrọ Ọlọrun ni ọna ti ko tọna, ki o si tun ni iriri ti awọn ti o n lo ọrọ rẹ ni ọna ti o tọna n ni. Amọ ṣa o, ayafi ti a ba fi aanu han si ọ, o di dandan ki o foju wina ewu ti o sorọ mọ ki a lo ọrọ rẹ ni ọna ti ko tọna, gẹgẹ bi Mose ati Aarọni ṣe foju wina rẹ.

Nibakanna, a le ma ṣe amulo ọrọ Ọlọrun ni ọna ti o tọ, ki a si tun ma ni iriri ti o tako nkan ti ọrọ rẹ sọ. Njẹ eyi wa jasi pe iriri wa ti sọ ọrọ Ọlọrun di eke bi? Rara o! Ki wa ni iṣoro? Ko si iṣoro kankan pẹlu wa tabi pẹlu ọrọ Ọlọrun ni irufẹ awọn akoko yi. Kiki nkan ti a nilo ni ki a mu suuru, ki a si duro ṣinṣin ni ṣiṣe amulo ọrọ rẹ ti a mọ ni ọna ti o tọ. Nigba ti asiko ba si to, a o jẹ ki iriri wa laye yi wa si ibamu pẹlu nkan ti Ọlọrun sọ.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, nigba ti Mose kọkọ mu ọrọ Ọlọrun tọ Farao, ọba Ijibiti, lọ lati tu awọn ọmọ Isiraẹli silẹ, nṣe ni nkan tun buru si fun awọn eniyan naa. Ṣe iriri wọn lasiko yẹn wa da ọrọ Ọlọrun duro lati tu wọn silẹ lẹyin-ọ-rẹyin bi? Rara o! Ọrọ rẹ papa tun wọn silẹ. Ṣugbọn Mose nilo lati duro ṣinṣin ni didojukọ Farao ati awọn ẹmẹwa rẹ pẹlu ọrọ gbogbo ti Ọlọrun n sọ fun titi a fi tu awọn ọmọ Isiraẹli silẹ.

Nitorina, awa naa gbọdọ di ọrọ yowu ti Ọlọrun ba ti sọ nipa aye wa mu ṣinṣin, ki a si tun ma doju ọrọ naa kọ awọn iṣẹlẹ aye wa, bi o tilẹ jẹ wipe iriri wa lodi si nkan ti O sọ. Idi si ni pe awọn iriri wa ko le sọ ọrọ Ọlọrun di yẹpẹrẹ tabi alailagbara. Ṣugbọn ọrọ rẹ, ti a ko ba yi ọkan wa pada nipa rẹ, di dandan ki o yi awọn iriri wa pada lati wa ni ibamu pẹlu ete rẹ rere fun aye wa. Bawo ni yoo ṣe wa gba wa ni asiko to lati dirọ mọ ọrọ Ọlọrun ki a ba le ni iriri rẹ? Nṣe ni a gbọdọ dirọ mọ ọn titi a o fi ni iriri rẹ. Adura mi si ni pe ki o ma fi gbogbo igba ni okun ati igboya ti o peye lati le ma ṣe ohun ti Ọlọrun sọ nipa ọrọ aye rẹ gbogbo, ki o ba le ni iriri ohun rere gbogbo ti O fẹ ki o ni iriri rẹ laye, bi o ti wu ki asiko naa ṣe bi igba ti o pẹ to. Amin.

Ki o ni ọsẹ rere.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Má lo ìrírí rẹ láti dájọ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ògún 20, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 16 Read More »

Mú sùúrù pẹ̀lú Ọlọ́run | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ògún 13, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 15

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ titi lailai lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu ayọ ti o ga ni mo fi ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ògún 2023. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ma fi gbogbo igba ṣe ọ yẹ pẹlu igbagbọ ati suuru ti o peye lati ri wọn gba ati lati jẹ igbadun wọn, gbogbo nkan rere ti O ti pese fun ọ lati ṣe oriire, ni orukọ Jesu. Amin.

Ọkan lara awọn nkan ti a kọ ninu Iwe mimọ ni pe igbagbọ ninu Ọlọrun nikan ko to lati ri awọn ileri ati ipese rẹ gba ati lati jẹgbadun wọn; a gbọdọ ni suuru pẹlu. Fun apẹrẹ, a sọ eyi fun wa ninu bibeli: “Ki ẹ ma ṣe di onilọọra, ṣugbọn alafarawe awọn ti wọn ti ipa igbagbọ ati suuru jogun awọn ileri. Nitori nigba ti Ọlọrun ṣe ileri fun Aburahamu, bi ko ti ri ẹnikan ti o pọ ju oun tikararẹ lati fi bura, o fi ara rẹ bura, wi pe, Nitootọ emi o bukun-fun ọ, emi o si sọ iru ọmọ rẹ di pupọ. Bẹẹ naa si ni, lẹyin igba ti Aburahamu ti suuru duro, o ri ileri naa gba.” (Hébérù 6:12-15)

Kini aṣẹ akọkọ ti a pa fun wa nibi yi? Ohun naa ni pe a ko gbọdọ ya ọlẹ ninu irinajo igbagbọ wa. Eyi jasi pe, a gbọdọ mu ibasepọ wa pẹlu Ọlọrun ni pataki, ki a si ma ṣe ohun gbogbo ti o tọ lati gbe e ro. A tun wa sọ fun wa pe ki a ṣe afarawe awọn ti wọn tipasẹ igbagbọ ati suuru jogun nkan ti Ọlọrun ṣe ileri fun wọn. Nitorina, igbagbọ ati suuru, ki i si ṣe igbagbọ nikan, gbọdọ ṣiṣẹ papọ ki a ba le ni iriri didara Ọlọrun ninu aye wa lẹkunrẹrẹ.

Wayi o, ọrọ Aburahamu ni a wa lo lati ṣe alaye eyi fun wa. Aburahamu, gẹgẹ bi a ti ṣe ri ninu Iwe mimọ, jẹ onigbagbọ ọkunrin lotitọ. Amọ ṣa, lati le ri ileri ọmọkunrin ti Ọlọrun ṣe fun un gba lati ipasẹ aya rẹ Sara, o ni lati fi suuru kun igbagbọ rẹ. Ṣugbọn Aburahamu naa ko fi gbogbo igba mu suuru pẹlu Ọlọrun. Nṣe ni o ni lati kọ ọ ni ọna ti o le. Nigba ti Ọlọrun kọkọ sọ fun pe Oun yoo fun ni ọmọkunrin kan ati pe Oun yoo sọ iru ọmọ rẹ di pupọ ni ilọpo-ilọpo nipasẹ ọmọkunrin naa, o gba a gbọ. Ọlọrun si mọ pe o gba Oun gbọ nitootọ. Nitorina, O ka igbagbọ rẹ si ododo fun un. (Wo: Jẹnẹsisi 15:1-6)

Amọ sa, lẹyin ọdun diẹ si, ara iyawo rẹ, Sara, ko balẹ mọ. O si wa gba a nimọran pe ki o dan ẹrubinrin rẹ, Hagari, wo, boya Ọlọrun le ti ipasẹ rẹ mu ileri rẹ ṣe. O si gbọ tirẹ, lailai ba Ọlọrun sọ ohunkohun nipa ọrọ naa ninu adura. Ṣibẹsibẹ, Hagari loyun fun un nitootọ, eyi ti o jẹ ki o dabi ẹni pe wọn wa ninu ifẹ Ọlọrun. Ṣugbọn laipẹ rara, awọn mejeeji ri pe awọn ti kuna. Kini idi? Hagari bẹrẹ si ni da wahala silẹ fun wọn, o n ṣe awọn nkan ti o le ba igbeyawo ọpọlọpọ ọdun wọn jẹ. Ti ko ba wa jẹ wipe o gba ki iyawo rẹ da sèríà fun ọdọmọbinrin yi ni, bi o tilẹ jẹ wipe inu oyun ni o wa, nṣe ni ile wọn ko ba doju-delẹ. (Jẹnẹsisi 16)

Ṣugbọn ki ni o ko wọn sinu gbogbo iyọnu yi? Ṣe aigbagbọ ninu Ọlọrun ni? Rara o! Dipo eyi, aimu suuru wọn pẹlu rẹ ni o fa. Wọn ni igbagbọ ninu Ọlọrun, wọn si n fi ọkan wa tan an lati fun wọn ni ọmọ ti wọn. Amọ dipo ki wọn mu suuru fun, wọn gbiyanju lati ran an lọwọ lati mu ileri rẹ fun wọn ṣe. Eyi si fẹrẹ le pa wọn run.

Ni kukuru, nigba ti o ṣe diẹ si, Ọlọrun farahan Aburahamu lẹkan si, O si jẹ ki o ye pe nṣe ni ko ba ti mu suuru. O sọ fun pe ọmọkunrin ti o tipasẹ Hagari bi, iyẹn Iṣimaẹli, ko ki i ṣe imuṣẹ ileri Oun fun un. Nitorina, yio si tun nilo lati duro diẹ si fun ọmọkurin eyi ti yoo jẹ imuṣẹ ileri Oun fun un lati de. Nigba ti o si ṣe eyi, a fi Isaki fun gẹgẹ bi ọmọkunrin ileri Ọlọrun.

Wayi o, o dami loju pe o gbọdọ jẹ nkan ti o le fun Aburahamu lati gba wipe Iṣimaẹli, ọmọkurin oun ti oun fẹran, ti oun si ti lo ọpọlọpọ ọdun lati tọju, ki i ṣe ààyò Ọlọrun fun mimu ileri ti O ṣe lati bukun fun gbogbo araye nipa iru ọmọ rẹ ṣẹ. Ṣugbọn ko si nkan ti o le ṣe nipa rẹ. O di dandan fun lati kọ ọmọkunrin alaiṣẹ naa ṣilẹ. Eyi si n fi han wa irufẹ irora ti a le mu wa sinu aye ara wa ati sinu aye awọn alaiṣẹ miran nipa aimu suuru wa pẹlu Ọlọrun. O le jẹ egbò ti ko ni san fun ọpọlọpọ iran ti o n bọ ni.

Nitorina, ti igbekẹle rẹ ba wa ninu Ọlọrun nitootọ fun imuṣẹ gbogbo ọrọ rẹ ni rere lori igbega rẹ, iṣoriire rẹ, ibalẹ-ọkan rẹ, ilera rẹ, aabo rẹ ati bẹẹ-bẹẹ lọ, o tun gbọdọ kọ bi a ti n mu suuru pẹlu rẹ, bi o ti wu ki asiko lọdi si ọ to. Ma ṣe gbiyanju lati ran an lọwọ nipa ole jija, titọ ile aláwo lọ tabi ṣiṣe agbere. O di dandan ki ṣiṣe eyi ko ọ sinu iyọnu bopẹ-boya, bi o tilẹ da bi ẹni pe o n ṣiṣẹ. Ọna kan ṣoṣo ti o fi le e ran an lọwọ ni ki o duro sinu ifẹ rẹ. Mo wa gbadura pe ki ọkan rẹ gba okun lati rin pẹlu suuru ninu ifẹ rẹ ni gbogbo igba, ni orukọ Jesu. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ aláyọ̀.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Mú sùúrù pẹ̀lú Ọlọ́run | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ògún 13, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 15 Read More »

Ọlọ́run ṣí i lójú | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ògún 06, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 14

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu oṣu Ògún 2023. Mo si wa gbadura pe ki Ọlọrun ṣi oju rẹ lati ri ohun gbogbo ti O ti pese silẹ fun ọ lati gberu ati lati jẹ igbadun aye rẹ ati ohun gbogbo ti o jẹ tirẹ ninu oṣu naa ati ni gbogbo eyi ti o ku ninu ọdun yi, ni orukọ Jesu. Amin.

Lẹyin igba ti Aburahamu ti ran Hagari ati ọmọ rẹ, Iṣimaẹli, lọ kuro ninu ile rẹ, awọn mejiji ranmu kaakiri inu aginju Baa-Ṣẹba titi omi mimu wọn fi tan. Nigbana ni ẹmi bẹrẹ si ni lọ kuro lara Iṣimaẹli ni oju iya rẹ. Nigba ti oju rẹ ko si gba a mọ, o gbe si abẹ igbo kan, o si ri jinna diẹ kuro lọdọ rẹ lati ṣọkun. (Wo: Jẹnẹsisi 21:14-16)

Ṣugbọn ṣe ọwọ nkan ti Hagari wa le ṣe niyi lati daabo bo ọmọkunrin rẹ? Rara o! Lotitọ, asiko naa ki i ṣe asiko idunnu fun wọn rara. A ṣẹṣẹ le wọn jade kuro ni ile Aburahamu ni, nibi ti wo ko ti ṣe alaini ifẹ ati ifọkanbalẹ. Nigba ti a o tun wa ba nkan jẹ, nṣe ni a tun le wọn jade lalai fun wọn ni nkankan bikoṣe ounjẹ diẹ ati igo omi kan. Lotitọ, wọn ko ki i ṣe ẹru mọ. Amọ ominira eniyan ti ko ni owo, ile tabi ibi ti yoo lọ ni wọn jẹ. Idi niyi ti wọn ṣe ranmu titi ninu aginju naa ti wọn fi lo omi wọn tan. Niwọn igba ti o si jẹ wipe inu aginju ni wọn wa, ko fi taarataara dabi ẹni pe wọn le ri omi mu rara. Nitorina, ipo ti ireti ti dopin ni wọn wa nitootọ.

Amọ ṣa o, Hagari ti ba Aburahamu gbe fun ọpọ ọdọ. Nitorina, ko si bi o ṣe fẹ sọ wipe ohun ko kọ nkankan nipa Ọlọrun rẹ, Ọlọrun alagbara, ti O sọ ọ di ọlọrọ, ti O si tun fun ni ọmọkunrin kan ni ọjọ ogbo rẹ. Ki a tilẹ sọ otitọ, idi ti ọmọ ti oun funrarẹ, iyẹn Iṣimaẹli, ṣe kọ ila abẹ ni pe Aburahamu jẹ olusin Ọlọrun yi. Ki wa lo de, nigbana, ti ko fi ke pe e fun iranwọ ati igbala ni asiko ti ko si ireti kankan fun mọ? Ki lo fa ti o ṣe sọ ireti nu, ti o si n duro ki iku mu ọmọkunrin rẹ lọ?

A ko ni idahun si awọn ibere wọnyi ninu bibeli. Amọ ṣa o, nkan ti o ṣẹlẹ si i fi han wa pe o ṣeeṣe ki eniyan mọ ọpọ nkan nipa Ọlọrun, ki o tilẹ tun ni awọn eniyan ni ayika rẹ ti o ti ni iriri agbara ati ojurere rẹ ni ọna ti o ga, ki o si tun ma ranti lati ke pe e ni asiko iṣoro rẹ. Ibi ti eyi ba si ti ri bẹ ẹ, afaimọ ki awọn iṣoro wa ma gbe wa mi lẹyin-ọ-rẹyin, ti a ko ba ṣaanu fun wa.

Hagari ko ba padanu ọmọkurin rẹ ati ẹmi ohun tikararẹ paapa lọjọ ti a n sọ yi, ti Ọlọrun ko ba lọ ṣaanu fun un. Lotitọ, awọn mejeeji ni o n sọkun. Ṣugbọn wọn ko ma a sọkun si Ọlọrun fun iranwọ. Wọn n sọkun nitori irora ati ainireti wọn ni. Amọ Ọlọrun, ti o pọ ninu aanu, tọ wọn wa, nigba ti o gbọ ẹkun Iṣimaẹli, O si fun wọn ni ọrọ itunu ati ireti. O sọ fun wọn pe Oun yoo sọ Ishmaẹli di orilẹ-ede nla. (Wo: Jẹnẹsisi 21:18)

Siwaju si, yatọ si pe O sọ fun Hagari ati Iṣimaẹli lati ma sọ ireti nu ṣugbọn ki wọn ma fojusọna si ọjọ ọla ti o logo, Ọlọrun tun ṣi oju Hagari lati ri kanga omi kan ti o wa pẹlu wọn ninu aginju ti wọn wa (Jẹnẹsisi 21:19). Iwọ naa gbe yẹwo. Ni gbogbo asiko ti awọn eniyan yi n sọkun, ti wọn si n ku lọ nitori ko si omi fun wọn lati mu, a ṣe kanga omi wa pẹlu wọn nibẹ, ninu eyi ti wọn ti le mu iye omi ti o ba wu wọn lati mu. Sibẹsibẹ wọn ko ri. Wọn ko ri nitoripe a ko ṣi oju wọn lati ri i. Ti Ọlọrun ko ba wa ṣaanu fun wọn, ki O si ṣi oju wọn lati ri i, nṣe ni wọn ko ba ṣegbe sinu aginju naa, bi o tilẹ jẹ wipe ohun ti wọn nilo lati wa láàyè wa nibẹ pẹlu wọn.

Ni ọna kanna, ti Ọlọrun ko ba ṣi oju wa lati ri awọn ipese rẹ kan fun igbadun wa, ilọsiwaju wa tabi ibalẹ ọkan wa, a le e ba ara wa ninu ijiya nibi ti o yẹ ki ma ti ṣe bi ọba. A si ri ọpọ ọmọ Ọlọrun kaakiri agbaye ti wọn n jiya lọwọlọwọ bayi nibi ti o yẹ ki wọn ti ma gbadun ara wọn. Boya ọkan lara wọn gan tilẹ ni iwọ naa.
O wa yẹ ki o la ẹnu rẹ, ki o si gbadura si Ọlọrun lati la oju rẹ lati ri awọn ipese rẹ fun ọ nibi ti o wa, dipo ti wa fi ma ronu nipa bi o o ti ṣe ṣipo lọ si ibomiran, bi ọpọ ti n ṣe loni.

Woo, ti oju rẹ ko ba la lati ri ipese awọn Ọlọrun fun ọ lati ṣoorire ninu aginju, ki ni idaniloju pe yoo la lati ri awọn ipese rẹ fun ni ibi ti o n pe ni ilẹ ọpọ ti o fẹ sa lọ? Ko si. Ṣe itiju nla kọ ni yoo wa jẹ fun ọ lati de ilẹ ọpọ, ki o si tun ma le ṣoriire nibẹ? Itiju nla ni yoo jẹ! Nitorina, dipo ti o o fi ma dakẹ jiya bi Hagari tabi ti o o ma ronu lati salọ, nṣe ni ki o la ẹnu rẹ, ki o si sọ fun Ọlọrun pe ki o ṣi oju rẹ lati ri gbogbo nkan ti O ti pese silẹ fun iwọ ati ile rẹ lati ṣoriire. Yoo si da ọ lohun, yoo si tun tẹ tabili ti o kun fun oniruuru adidun fun ọ ninu aginju rẹ.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ọlọ́run ṣí i lójú | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ògún 06, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 14 Read More »