September 2023

Kò sí ọ̀nà-àbùjá sí ìdàgbàsókè | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwàrà 01, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 22

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lailodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa ati Olugbala wa. Mo ki ọ kaabọ sinu oṣu Ọ̀wàrà 2023, oṣu ayajọ ominira fun Naijeria. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun kun aye ati ile rẹ pẹlu adun ati isinmi ni ojoojumọ oṣu naa, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, bi oni tilẹ jẹ ọjọ naa ti o pe ọdun mẹtalelọgọta ti orilẹ-ede yi ti gba ominira, ọpọ ni ko ri nkankan ninu ominira naa ti o yẹ ki gba ilu, ki a si ma jo le lori. Ki ni idi? Idi ni pe ominira wa ko ti yọri si idagbasoke ati ilọsiwaju ti o giriki fun wa gẹgẹ bi orilẹ-ede. Ki si ni idi ti ko ṣe ti yọri si awọn nkan wọnyi fun wa? Pataki julọ lara idi naa ni wipe, gẹgẹ bi adari ati awọn ti wọn n dari, a ko fi ara wa jin lati ma ṣe awọn nkan ti yoo yọri si idagbasoke ati ilọsiwaju.

Wo o, idagbasoke ati ilọsiwaju ko ki i waye lasan tabi ni pajawiri. Awọn nkan wa ti o ma n jẹ ki wọn waye. Lotitọ o, ti a ba ni ki a lọ ki a bọ, Ọlọrun naa ni O ma n mu ki ohun gbogbo dagba soke (1Kọrinti 3:6-7). Amọ ṣa o, bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun ni O ma n jẹ ki ohun gbogbo dagba soke, awọn nkankan si wa ti O fẹ ki a ṣe ki iye rẹ ba le ṣiṣẹ ninu wa tabi ninu ohun yowu ti a n ṣe, ki o si mu dagba soke.

Fun apẹrẹ, bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun ni O ma n jẹ ki awọn ọmọde-jojolo wa dagba soke ninu ara, ninu ọgbọn ati ninu imọ, a gbọdọ fun wọn ni ounjẹ ti o peye, ki a fi aye silẹ fun wọn lati kọ oniruuru ẹkọ, ki a si tun ki wọn laya lati ma ṣe ere idaraya. Aijẹbẹ, idagbasoke ti wọn ni amuyẹ lati ni ko ni farahan. Eyi ko si ni jẹ ẹbi Ọlọrun.

Nitorina, ti a ba fẹ ki orilẹ-ede wa dagba soke, ki o si di nla laarin awọn orilẹ-ede aye yoku, gbogbo wa gbọdọ ṣe idamọ awọn nkan ti yoo gbe idagbasoke rẹ larugẹ, ki a si fi ara wa jin lati ma a ṣe wọn. Eyi si gbọdọ ṣuyọ ninu irufẹ awọn adari ti a o ma a yan ni asiko idibo wa. A ko le ma fi igba gbogbo yan awọn alanikanjọpọn, olojukokoro ati alainikanṣe eniyan gẹgẹ bi adari, ki a si tun ma reti pe ki wọn ṣe nkan ti yoo yọri si igbega orilẹ-ede wa. A o fẹrẹ nilo to ẹgbẹrun iṣẹ iyanu ki eyi to le waye.

Nibakana, ti a ba fẹ dagba soke ninu ẹmi, gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun, a gbọdọ fi ara wa jin fun awọn nkan ti yoo yọri si idagbasoke wa. Lotitọ, Ọlọrun fẹ ki a dagba soke ninu irinajo wa pẹlu rẹ. Ko fẹ ki a joko si ipo arobo, lẹyin igba ti a ti tun wa bi. Aijẹbẹ, a ko ni le gbe igbe aye ti ko ni ja a kulẹ ninu aye yi. Idi si niyi ti O ṣe paṣẹ fun wa ninu ọrọ rẹ lati dagba soke ninu oore-ọfẹ ati imọ ọmọ rẹ Jesu Kirisiti (2Peteru 3:18).

Ṣugbọn Ọlọrun ko ni mu wa ni tipatipa lati dagba soke ninu ẹmi. Awọn nkan wa ti a gbọdọ ṣe ki eyi ba a le waye. A si sọ awọn nkan wọnyi fun wa ninu bibeli. A sọ fun wa pe ki a fi ara wa jin fun ọrọ Ọlọrun, adura gbigba ati ibaṣepọ pẹlu awọn ọmọ Ọlọrun. Ti ko ba wa jẹ wipe a fi ara wa jin fun awọn nkan wọnyi, Ọlọrun funrarẹ gan ko ni le mu wa dagba soke ninu igbagbọ wa ati ninu iwulo wa fun un.

Nikukuru, nkan ti mo n sọ ni pe irufẹ idagbasoke yowu ti a le fẹ ki o ṣẹlẹ ninu aye wa, a gbọdọ ṣe idamọ awọn nkan ti a nilo lati bẹrẹ si ni ṣe ki o ba le waye. Wayi o, o wa le gba asiko diẹ ki awọn igbasoke kan ti o n waye ninu aye wa to fi ara han, bi a tilẹ n ṣe awọn nkan ti yoo jẹ ki wọn waye. Ṣugbọn niwọn igba ti idagbasoke ba ti n ṣẹlẹ ninu aye wa, o di dandan ki o farahan ni asiko kan wipe a n dagba soke lotitọ.

Nitorina, bi ko ba tilẹ han si ọ tabi si ẹnikẹni ni ayika rẹ pe o n dagba soke ninu ẹmi ati ni awọn abala aye rẹ miran, ma ṣe dẹkun lati ma ṣe awọn nkan ti yoo jẹ ki o dagba soke. Dipo bẹ ẹ, tẹsiwaju lati ma a ṣe wọn. Nigba ti akoko ba si to, idagbasoke ati ilọsiwaju rẹ yoo di mimọ fun gbogbo eniyan. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ṣi oju wa lati ri ohun gbogbo ti a nilo lati ṣe ki a ba le ni iriri idagbasoke ati ilọsiwaju otitiọ ninu aye wa, ile wa ati orilẹ-ede wa, ki O si tun fun wa ni okun lati fi ara wa jin lati ma a ṣe awọn nkan wọnyi. Amin.

A ku ọdun ominira.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Kò sí ọ̀nà-àbùjá sí ìdàgbàsókè | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwàrà 01, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 22 Read More »

Má sọ ààyè rẹ nù

Rí i dájú pé ò ń kẹ́kọ̀ ọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 24, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 21

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ titi lailai lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati nipasẹ Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o kẹyin oṣu Owewe 2023. Adura ma si ni pe ki Ọlọrun kọ ọkan rẹ ni bi o ti le ṣe amulo ti o peye gbogbo ipese rẹ fun ọ lati gbe igbe aye ti o nitunmọ ati igbe aye itayọ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ọkan lara idi ti ọpọ ti o jẹ Kirisitiẹni ko ki i ṣe ni iriri agbara ati didara Ọlọrun bi a ti ṣe ileri pe o yẹ ki o jẹ ninu Iwe Mimọ ni pe wọn ko ki i fi ara wọn jin lati kẹkọ lọdọ rẹ nipa bi wọn ti le ni awọn iriri yi. Bi a ti ṣe ri ninu Iwe Mimọ, awọn nkan meremere ti Ọlọrun ni ni ipamọ fun awọn ti o fi igbẹkẹle wọn sinu rẹ kọja nkan ti a le ka tabi fi oye wa gbe (Saamu 40:5; 1Kọrinnti 2:9). O si tun wa ti fi ara rẹ jin lati ri wipe a ri awọn nkan wọnyi gba ati wipe a jẹ igbadun gbogbo wọn.

Amọ ṣa o, a ni lati kọ bi a ti ṣe n ri nkan gba lọwọ rẹ ati bi a ti ṣe n jẹ igbadun awọn nkan ti O ti pese fun wa. Fun apẹrẹ, nigba ti o ku diẹ ki iṣẹ iranṣẹ Wolii Elija pari ninu aye yi, Ọlọrun sọ fun pe ki o lọ ya Eliṣa, ọmọ Ṣafati, sọtọ lati rọpọ rẹ gẹgẹ bi aṣiwaju laarin awọn wolii ni Isiraẹli. O si lọ, o si ya a sọtọ ni gbangba, bi ko tilẹ lo ororo ṣugbọn agbada rẹ, ninu oko rẹ, gẹgẹ bi Ọlọrun ti pa a lasẹ fun un. (Wo: 1Awọn Ọba 19:15-19)

Wayi o, Eliṣa, lẹyin igba ti a ti ya a sọtọ bi eyi tan ni gbangba-gbàǹgbà, le bẹrẹ si ni lọ kaakiri orilẹ-ede rẹ, ki o si ma sọ fun ẹnikẹni ti o ba pade pe ki wọn ma pe oun ni ‘Wolii Eliṣa’ ati ‘aayo Ọlọrun lati rọpọ Elija’. Ki wa ni eyi ko ba yọri si? Ijamba iṣẹ iransẹ! Kini idi? Idi ni pe bi o tilẹ jẹ wipe Elija ti ya ọkunrin yi sọtọ gẹgẹ bi wolii ti yoo rọpo rẹ ni ọjọ naa ti o wa a kan, aṣẹ ati agbara lati ṣiṣẹ gẹgẹ bi wolii yii ko ba le lọjọ ti a n wi yi. Yatọ si eyi, bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun ti yan an gẹgẹ bi wolii, gbogbo nkan ti o mọ lasiko naa ko kọja iṣẹ agbẹ, eyi ti o si yatọ si ki a duro gẹgẹ bi agbẹnusọ fun Ọlọrun.

Ki Eliṣa ba wa le duro gẹgẹ bi agbẹnusọ fun Ọlọrun, o nilo lati kẹkọ. Aijẹbẹ, o ṣeeṣe ki Ọlọrun kọ ọ silẹ nikẹyin-kẹyin, ki O si fi ẹlomiran rọpo rẹ, gẹgẹ bi o ti ṣẹlẹ si Ọba Sọọlu. Eliṣa naa funrarẹ, lọna kan tabi omiran, si wa mọ eyi. Nitorina, o fi iṣẹ rẹ gẹgẹ bi agbẹ silẹ, o tẹle Elija, o si di iranṣẹ rẹ ki o ba le kẹkọ lati ọdọ rẹ nipa bi o ti ṣe le di irufẹ wolii ti Ọlọrun yan an lati jẹ. (Wo: 1Awọn Ọba 19:20-21)

Ṣe igbesẹ yi wa lere lori fun Eliṣa tabi ko ni i? O ni i. Idi si ni pe, bi a ti ṣe fi han wa siwaju si ninu Iwe Mimọ, ni ọjọ ti Ọlọrun n gba Elija soke, o jẹ ki o ye Eliṣa pe bi o tilẹ jẹ wipe oun ti ko ipa ti oun lati fi han ni gbangba gẹgẹ bi wolii ti yoo rọpo oun, ko si ni ikawọ oun lati fun ni aṣẹ ati agbara ti o nilo fun ipo yi. Iṣẹ Ọlọrun ni eyi jẹ. Ti ko ba si ni ṣe e, a jẹ wipe o ṣeeṣe ki O ti yan ẹlomiran fun ipo na niyẹn. (Wo: 2Awọn Ọba 2:1-15)

Awa dupẹ pe, ni ọjọ ti a n wi yi, Eliṣa jẹwọ pe oun ti kọ ẹkọ to lọdọ Elija lati le ri ohun ti o nilo lati ri ki o ba le gba aṣẹ ati agbara ti o nilo lati duro gẹgẹ bi adari awọn wolii ni Isiraẹli. Nitorina, o tẹsiwaju lati sin Ọlọrun lotitọ lati ibẹrẹ de opin. Ko fi idibajẹ sinu ipo rẹ gẹgẹ bi wolii tabi ko ṣi ipo naa lo. Dipo eyi, o lo ipo naa lati mu aye san si fun awọn eniyan rẹ.

O wa ṣeni laanu pe a ko le sọ nkan kan naa nipa Gehasi, ọmọkunrin ti o pada di iranṣẹ Eliṣa. Bi o tilẹ jẹ wipe gbogbo igba ni o fi wa pẹlu wolii yi, ti o si tun n tẹle lọ si ibikibi ti o ba lọ, ko kọ ẹkọ kankan ti o lojutu to lati le rọpo rẹ gẹgẹ bi asiwaju wolii Ọlọrun ni Isiraẹli. Dipo eyi, nṣe ni o fi idibajẹ si oju ọna ara rẹ pẹlu ojukokoro ti o si di adẹtẹ. Nitorina, dipo ki o fi di ẹni ti Ọlọrun yan an lati jẹ, nṣe ni o gbẹyin aye rẹ gẹgẹ bi olusọtan ninu aafin ọba Isiraẹli. O ma ṣe o! (Wo: 2Awọn Ọba 5 & 8:1-6)

Ni kukuru, ni ibamu pẹlu awọn nkan wọnyi, Jesu Oluwa wa sọ fun wa pe, “Ẹ wa sọdọ mi gbogbo ẹyin ti n ṣiṣẹ, ti a si di ẹru wuwo le lori, emi o si fi isinmi fun yi. Ẹ gba ajaga mi si ọrun yin, ki ẹ si maa kọ ẹkọ lọdọ mi nitori oninu tutu ati onirẹlẹ ọkan ni emi; ẹyin o si ri isinmi fun ọkan yin. Nitori ajaga mi rọrun ẹru mi si fuyẹ.” (Matiu 11:28-30) Njẹ o ri bayẹn? Ti a ba fẹ jẹ igbadun isinmi lati ọdọ Jesu Oluwa wa, ki a si tun da ohun gbogbo ti Ọlọfun fẹ ki a da laye yi, wiwa sọdọ rẹ ko to rara. A tun gbọdọ rẹ ara wa silẹ lati kẹkọ lọdọ rẹ, bi Eliṣa ti ṣe fi irẹlẹ kẹkọ lọdọ Elija. Aijẹbẹ, wiwa wa si ọdọ rẹ le ma gbe nkankan ti o ni itunmọ ṣe ninu aye wa.

Nitorina, ri daju pe, dipo ti iwọ yoo fi ma tan ara rẹ jẹ, o n kẹkọ lọdọ Jesu Oluwa wa lotitọ lori ohun gbogbo ti o nilo lati jẹ igbadun ẹkunrẹrẹ Ibukun ti Ọlọrun ti fi fun ọ ati lati di ẹni ti O fẹ ki o jẹ laye yi. Ki o si ma fi ojoojumọ gba okun lati ọdọ Ẹmi Ọlọrun lati mu ọrọ yi ni pataki, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Rí i dájú pé ò ń kẹ́kọ̀ ọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 24, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 21 Read More »

Má sọ ààyè rẹ nù

Mú wọn wá sọ́dọ̀ rẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 17, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 20

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lailodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Owewe 2023. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun ri ọ lo lọna ti o ga ninu ọsẹ naa lati dari ọpọ lati ni iriri didara ọmọ rẹ, Jesu Kirisiti. Amin.

Bi a ti ṣe fi han wa ninu bibeli, ọkan lara idi ti Jesu Oluwa wa ṣe ni ọpọ ti o n tọ ọ wa lati gba nkan kan tabi omiran lọwọ rẹ ni pe awọn ti o ti jẹ anfaani iṣẹ iranṣẹ rẹ ko dẹkun lati ma sọ fun awọn ọrẹ ati ebi wọn ati lati ma mu wọn tọ ọ wa. Fun apẹrẹ, Maaku fun wa ni iroyin yi nipa asiko kan ti Jesu wa si ile:

“Awọn ọkunrin kan wa, wọn gbe arọ tọ ọ wa, ẹni ti ọkunrin mẹrin gbe. Nigba ti wọn ko si le de ọdọ Jesu, nitori ọpọ eniyan, wọn da orule ile lu ni ọgangan ibi ti Jesu wa. Wọn si sọ ọkunrin arọ naa kalẹ ti oun ti ẹni rẹ niwaju Jesu. Nigba ti Jesu si ri igbagbọ wọn, o sọ fun arọ naa pe, “Ọmọ, a dari gbogbo ẹṣẹ rẹ ki ọ.”” (Máàkù 2:3-5)

Njẹ o ri bayẹn? Idi kan ṣoṣo ti ọkunrin arọ yẹn ṣe ni anfaani lati gba iwọsan lati ọwọ Jesu Oluwa wa ni pe awọn eniyan rẹ gbe wa si ile rẹ. Ṣugbọn wọn ko kan gbe wa si ile Oluwa nikan, wọn tun sa gbogbo ipa wọn lari ri Jesu. Oluwa si tọka si nkan ti wọn ṣe yi si igbesẹ igbagbọ. Nitorina, ko ki i ṣe igbagbọ ọkunrin arọ yi ni Oluwa wo lati wo o san bikoṣe igbagbọ awọn ti o gbe wa si ọdọ rẹ.

Lafikun, Johanu sọ fun wa ninu iyinrere rẹ nipa bi Anderu, lẹyin igba ti o ti pade Jesu, ṣe lọ lẹsẹkẹsẹ lati wa arakunrin rẹ, Simoni, ati lati mu wa sọdọ Oluwa. Nigba ti o si de ọdọ rẹ, O fun ni orukọ tuntun. O pe e ni ‘Peteru’. Nitorina, idi ti a ṣe n sọrọ nipa Apọsiteli Peteru nla ni ni pe arakunrin rẹ mu wa sọdọ Jesu Oluwa wa lati ni iriri igbala ati didara rẹ. (Wo: Johanu 1:40-41)

Siwaju si, Johanu sọ fun wa nipa bi Filipi ṣe mu ọrẹ rẹ Nataniẹli wa sọdọ Jesu Oluwa wa. Bi o si wa tilẹ jẹ wipe Nataniẹli kọkọ kọminu nipa pipade Oluwa, ọrẹ rẹ rọ ọ lati wa lati pade rẹ naa ki o to pinnu lori ọrọ rẹ. Wayi o, lẹyin igba ti o wa, ti Oluwa si fun ni awọn ifihan kan nipa ara rẹ, o jọwọ ara rẹ fun gẹgẹ bi Oluwa rẹ lati ọjọ naa lọ, o si tun wa di ọkan lara awọn apọsiteli rẹ. (Wo: Johanu 1:43-51)

Njẹ bi o tilẹ wa jẹ wipe Oluwa wa ko si ninu aye yi lọwọ-lọwọ yi nipa ti ara, gbogbo igba ni O ma n wa ninu gbogbo ipade awọn ti o gbagbọ ninu rẹ nipasẹ Ẹmi rẹ. O ma n wa nibẹ lati kọ, wosan, tu silẹ ati yi aye awọn ti o wa ninu awọn ipade wọnyi pada. Ti iwọ naa ba ti wa n ni iriri didara ati iyipada rẹ ninu aye rẹ ninu ijọ yi, o yẹ ki iwọ naa ma mu awọn ọrẹ rẹ, ẹbi rẹ ati awọn aladugbo rẹ tọ ọ wa lati ni iriri kan naa, ki o si ma jẹ alanikanjọpọn. (Wo: Mátíù 18:20)

Wo o, o ko le sọ bi nkan ti Oluwa le ṣe fun awọn yowu ti o ba mu tọ ọ wa ṣe le ga to. O ko le sọ bi mimu wọn wa sọdọ rẹ ṣe le yi aye wọn, ile wọn ati ọjọ-ọla wọn pada. Ṣe Anderu le sọ pe arakunrin rẹ, Peteru, yoo jẹ ẹni ti Oluwa yoo lọ ni ọna ti o ga ti O gba lo o nigba ti o kọkọ mu wa sọdọ rẹ? Ko le sọ! Ṣugbọn nipa mimu wa sọdọ rẹ, o ṣi ilẹkun silẹ fun lati di irinṣẹ iyin ti o ga lọwọ rẹ.

Nibakana, nipa mimu awọn ọrẹ, ẹbi ati aladugbo rẹ wa sọdọ Oluwa, o ṣeeṣe ki iwọ naa ṣi ilẹkun silẹ fun wọn lati di irinṣẹ iyin ti o ga ni ọwọ rẹ. Nitorina, bi o ti ṣe n lọ ni ọṣẹ yi, bẹrẹ si ni wo awọn ti iwọ naa yoo mu wa si ọdọ Oluwa laarin awọn ti o wa ni ayika rẹ. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun fi aaye gba ọ lati le mu wọn wa sọdọ rẹ, ki O si tun kun ọ pẹlu ọgbọn ati igboya ti o peye lati ṣe bẹẹ gẹgẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ ti larinrin.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Mú wọn wá sọ́dọ̀ rẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 17, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 20 Read More »

Ya ara ya ìmọtaraẹninìkan | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 10, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 19

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Òwewè 2023. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun ya ọkan rẹ ya ohun gbogbo ti ko tọ ti o n jẹ ki awọn ibaṣepọ rẹ kan, ti o si tun n di iriri didara rẹ lọwọ ninu aye rẹ. Amin.

Wayi o, ọkan lara awọn nkan ti o ma n jẹ ki o ṣoro fun wa lati ni ibaṣepọ ti o larinrin pẹlu awọn ti o wa ninu aye wa ni imọtaraẹninikan. Ki ni imọtaraẹninikan? Imọtaraẹninikan ni ki a lọ fun nkan ti a fẹ lalai bikita nipa ọna ti yoo gba pa awọn miran lara. Eyi jasi pe, o ṣa fẹ nkan ti o fẹ ni, o ko si bikita boya eyi pa ẹnikẹni lara tabi pa wọn run.

Nitorina, imọtaraẹninikan ni ipilẹ fun gbogbo iwa ibi ti a n wu laye. Oun ni idi ti awọn eniyan ṣe n jale, ṣe iṣekuṣe, fi ipa bani lopọ, paniyan, ṣẹ oṣo owo ati bẹẹbẹẹ lọ. Wọn kan ṣa fẹ nkan ti wọn fẹ fun ara wọn ni. Wọn ko si bikita nipa nkan ti wọn nilo lati ṣe lati ni i ati bi ọna ti wọn gba lati ni nkan yi ṣe le pa awọn miran lara. Tara wọn nikan ni wọn mọ.

Imọtaraẹninikan, bi mo ti ṣe sọ tẹlẹ, naa ni idi ti awọn eniyan ko ṣe le fi irẹpọ gbe ninu igbeyawo wọn, ni adugbo wọn, ni ibi iṣẹ wọn ati ninu ijọ Ọlọrun wọn pẹlu. Ohun kan ṣoṣo ti wọn ma n ro ko ju nkan ti wọn fẹ lọ ati bi wọn yoo ti ṣe ri i. Wọn ko ni ronu nipa bi oun ti wọn fẹ ati ọna ti wọn gba lati ri yoo ṣe pa awọn ti o wa pẹlu wọn tabi ni ayika wọn lara. Nitorina, o di dandan ki wọn ba atako pade, eyi ti o si le lewu tabi ki o na wọn ni nkan ti o pọ jọjọ.

Ni ọdun melokan ṣẹyin, oorun buruku kan ti ko ṣe farada rara ni o ki mi nigba ti mo pada de lati ibi iṣẹ. “Kini o ṣẹlẹ nibi?” mo bere lọwọ awọn ti a jọ n gbele. “Ki lo de ti oorun buruku yi ṣe gba ibi gbogbo kan?” Wọn si sọ fun mi pe awọn ara ile ti o wa lẹgbẹ wa ni o ko ṣalanga wọn, ti wọn si da omi rẹ si oju ọna wa.

Ki wa lo fa ti wọn ṣe ṣe eyi? Ṣe wọn ronu nipa bi nkan ti wọn ṣe yi ṣe le pa ilera wọn ati ti awọn aladugbo wọn lapapọ lara? Irọ o! Ṣe wọn tilẹ ro wipe oorun ti o n jade lati ipasẹ nkan ti wọn ṣe yi yoo le gbogbo awọn ti o wa ni adugbo kuro ni ile wọn? Irọ o! Awọn kan ṣa ri wipe iho ti o n gba omi ile igbọnsẹ wọn ti kun, o si nilo ki wọn ko o. Nitorina, wọn ko o, wọn si da a si oju ọna. Eyi si wa jẹ ki awọn aladugbo kan ke si awọn oṣiṣe eto ilera ti ijọba melokan lati wa bẹ wọn wo ati lati fun wọn ni ijiya ti o tọ.

Ki wa ni koko ọrọ mi? Oun naa ni pe imọtaraẹninikan yoo mu ki aye ṣoro fun iwọ ati awọn ti o wa ni ayika rẹ. Idi si ni yi ti ọrọ Ọlọrun ṣe sọ fun wa pe, “Ẹ ma ṣe ohunkohun ninu ilepa-ara tabi ogo asan, ṣugbọn ni irẹlẹ ọkan ki olukuluku ro awọn ẹlomiran si ẹni ti o san ju oun lọ. Ki olukuluku yin ma ṣe ro ohun ti ara rẹ nikan, ṣugbọn ti ẹlomiran pẹlu.” (Fílípì 2:3-4) Njẹ o ri bayẹn? Ti a ba fẹ alaafia ni ile wa, ni adugbo wa, ni ibi iṣẹ wa ati ninu ijọ wa, ẹnikọọkan wa ko gbọdọ ma lepa ohun ti o fẹ fun ara rẹ nikan ṣugbọn ohun ti awọn miran naa fẹ fun ara wọn pẹlu.

Se o ri, ti ko ba ki i ṣe ọrọ ti ara wa nikan ni a mọ, ti ọrọ ti awọn miran naa jẹ wa logun pẹlu, a o fi iṣọra ati oye ba wọn lopọ. Nitorina, a ko ni gbe igbesẹ ti yoo pa wọn run nigba ti a ba n gbiyanju lati tẹ ara wa lọrun tabi ki a ma fi ẹtanu ba wọn lo ti wọn ba nilo lati kọ lati fun wa ni awọn nkan kan ti a tọrọ lọwọ wọn. Ṣugbọn ti a ba n gbe igbesẹ ti o n pa aye tabi ayọ awọn miran run nitoripe a fẹ tẹ ara wa lọrun tabi ti a ba n sọ awọn miran di ọta wa nitoripe wọn ko fun wa ni awọn nkan kan ti a bẹbẹ fun (awọn nkan ti ko ki ṣe ẹtọ wa), nṣe ni a n rin ninu imọtaraẹninikan. Bi o ti wa wu ki a lọ soke to ni aye yi, ibanujẹ ati irora ko ni jina si aye wa.

Nitorina, ṣe ayewo aye rẹ fun oniruuru imọtaraẹninikan ti o le wa nibẹ, ki o si ri daju pe o mojuto pẹlu ọrọ Ọlọrun ati pẹlu agbara Ẹmi rẹ. Ki Ọlọrun si fun ọ ni okun lati ṣe eyi. Amin.
Ki o ni ọṣẹ ti o ga.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ya ara ya ìmọtaraẹninìkan | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 10, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 19 Read More »

Ànfààní fún un láti ṣiṣẹ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 03, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 18

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. O dun mọ mi ninu lati ki ọ kaabọ sinu oṣu Òwewè 2023. Adura mi si pe ki Ọlọrun ṣe ara rẹ logo ni ọna ti o han kedere ni gbogbo abala aye rẹ ninu oṣu naa ati ni gbogbo eyi ti o ku ninu ọdun yi. Àmín.

Bi a ti ṣe ri ninu Iwe mimọ, aye ti a n gbe inu rẹ yi jẹ eyi ti o wa labẹ agbara Satani (1Jòhánù 5:19). Idi si niyi ti ko fi si ibi kankan laye naa ninu eyi ti iṣẹ ika rẹ ko ti ma fi ara han. Amọ ṣa o, Ọlọrun, ninu aanu rẹ, ti ran ọmọ rẹ lati pa awọn iṣẹ ẹda buburu ati ika yi run (1Jòhánù 3:8). Ibikibi ti awọn eniyan ba si ti fi aaye gba a lati ṣiṣẹ, o di dandan ki iṣẹ Satani di piparun nibẹ, ki Ọlọrun ṣi jẹ ṣiṣe logo.

Fun apẹrẹ, Johanu fun wa ni akọsilẹ yi nipa ọkunrin kan ti Jesu Oluwa wa wosan:

“Bi o si ti n kọja lọ, o ri ọkunrin kan ti o fọju lati igba ibi rẹ wa. Awọn Ọmọ ẹyin rẹ si bi i leere, pe, “Olukọ, ta ni o dẹsẹ, ọkunrin yii tabi awọn obi rẹ, ti a fi bi i ni afọju?” Jesu dahun pe, “ki i ṣe nitori pe ọkunrin yii dẹṣẹ, tabi awọn obi rẹ: ṣugbọn ki a baa le fi iṣẹ Ọlọrun han lara rẹ. Awa ni lati ṣe iṣẹ ẹni ti o ran mi, niwọn igba ti o ba ti jẹ ọsan: oru n bọ wa nigba ti ẹnikan ki yoo le ṣe iṣẹ.”” (Jòhánù 9:1-4)

Njẹ o ri bayẹn? A bi ọkunrin yi ni afọju, ṣugbọn ko ki i ṣe nitori ẹṣẹ ẹnikẹni bikoṣe nitori pe Satani kọlu u. Nitorina, ko ki i ṣe gbogbo igba naa ni ẹṣẹ ma n wa nidi ipọnju awọn eniyan. Awọn igba ma n wa ti o jẹ wipe awọn eniyan a ma jiya nitoripe Satani kan fẹ fiya jẹ wọn ni. Ti wọn ko ba si mọ bi a ti ṣe n kọju ija si, ki wọn si kọju ija si, yoo ṣe aṣeyọri lati fi iya jẹ wọn, ti Ọlọrun ko ba da a duro. Nkan ti o ṣẹlẹ si Jobu niyẹn. Nkan ti o si ṣẹlẹ bakanna si ọkunrin ti a n sọrọ rẹ yi niyẹn.

Satani kọlu ọkunrin yi nigba ti o si wa ninu iya rẹ lati sọ ọ di afọju. Ọna ti o wa gba ṣe eyi ni a ko mọ. Ṣugbọn kedere ni o han si wa pe awọn obi arakunrin yi ko kọju ija si. Ki ni idi? Ni kukuru, idi kan ti o le jẹ naa ni pe awọn naa, gẹgẹ bi awọn apọsiteli Oluwa, gbagbọ pe iya ẹṣẹ ara rẹ tabi ti wọn ni o n jẹ. Niwọn igba ti eyi si ri bẹ, wọn ko le ri Satani rara ninu ọran naa. Nkan kan ṣoṣo ti wọn le ri ni pe Ọlọrun n fi iya jẹ ẹ nitori ẹṣẹ wọn. Nitorina, ireti kan ti wọn le ni naa ko ju pe yoo boju aanu wo wọn lọjọ kan, yoo si mu ọwọ idajọ rẹ kuro lara ọmọkunrin naa.

Amọ ṣa o, nigba ti Jesu da si ọrọ naa, o yi gbogbo ero wọn pada. Akọkọ, O jẹ ki o ye awọn ọmọ ẹyin rẹ pe ọmọkunrin yi ko si ni ipo ti o wa yi nitori ẹṣẹ rẹ. Ekeji, O sọ fun wọn pe ohun ti o ṣẹlẹ si ko ki i ṣe iṣẹ Ọlọrun ṣugbọn ti eṣu. Ẹkẹta, O fi han wọn pe iṣẹ eṣu, bi ifọju arakunrin yi, ma n fun Ọlọrun ni anfaani lati ṣe iṣẹ igbala ati itusilẹ tirẹ. Ẹkẹrin, O fi han wọn pe idi ti Oun ṣe wa ninu aye ni lati ṣe iṣẹ Ọlọrun laarin awọn eniyan. Ṣe O wa ṣe iṣẹ Ọlọrun ninu aye ọkunrin yi tabi ko ṣe? O ma ṣe e. O ri daju pe o bẹrẹ si ni riran lati ọjọ naa lọ. Eyi si jẹ ki Ọlọrun jẹ ṣiṣe logo lati ọwọ ọkunrin yi, awọn obi rẹ ati awọn alabayọ miran. (Wo: Johanu 9:6-38)

Nibakanna, Ọlọrun n wọna bi yoo ṣe jẹ ṣiṣe logo ninu aye iwọ naa nipa pipa ohunkohun ti o ba jẹ iṣẹ ti Satani ti ṣe tabi ti o n ṣe ninu rẹ run. Ko si wa bikita boya ẹṣẹ ni o fa iṣẹ rẹ ninu aye rẹ tabi ẹṣẹ kọ. Kiki nkan ti O fẹ ni ki o mọ pe ohun yowu ti Satani ba n ṣe ninu aye rẹ jẹ anfaani fun lati ṣiṣẹ ninu aye rẹ ati lati jẹ ṣiṣe logo. Nitorina, fi aye gba a lati ṣiṣẹ ati lati yi nkan pada si rere fun ọ.

Bawo wa ni a ṣe le fi aye gba Ọlọrun lati ṣiṣẹ ninu wa ati lati pa iṣẹ eṣu run? Akọkọ, a le fi aye gba a nipa sisọ fun pe ko ṣe bẹ. Nitorina, gbadura si nipa iṣẹ yowu ti o ba kẹfin pe eṣu n ṣe ninu aye rẹ, ki o si sọ fun pe ki O pa a run. Yoo si ri bẹ. Siwaju si, a tun le fi aye gba a lati ṣiṣẹ nipa ṣiṣe ohunkohun ti O ba sọ fun wa pe ki a ṣe. Bi a ti ṣe ri ni ti ọrọ ọmọkunrin afọju yẹn, Oluwa sọ fun pe ki o lọ wẹ ninu adagun Omi Siloamu. Nigba ti o si lọ, o pada wa sile gẹgẹ bi ẹni ti o n riran. Ti awa naa ba si le mu ohunkohun ti O ba sọ fun wa nipa igbala, iṣoriire ati iwosan wa ni pataki, ki a si ṣiṣẹ le lori, iṣẹ rẹ yoo faharan ninu aye wa, awọn eniyan yoo si ṣe e logo lati ipasẹ wa.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ aláyọ̀.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ànfààní fún un láti ṣiṣẹ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 03, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 18 Read More »