October 2023

Má ṣe gbẹ́yìn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwàrà 29, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 26

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lẹkunrẹrẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo ki ọ kaabọ pẹlu inu didun sinu ọsẹ ti o so oṣu Ọ̀wàrà ati Belu 2023 pọ mọ ara wọn. Adura mi fun ọ si ni pe ki o ṣe aṣeyọri ninu gbogbo ifẹ Ọlọrun fun aye rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, ọkan lara awọn nkan ti o duro fun ifẹ Ọlọrun fun aye rẹ ni ki o tayọ ninu ifarajin rẹ lati ma gbe awọn ti o n bọ ọ pẹlu ọrọ Ọlọrun larugẹ pẹlu awọn nkan ini rẹ. Wo nkan ti ọrọ Ọlọrun sọ nipa eyi: “Ṣugbọn ki ẹni ti a n kọ ninu ọrọ naa maa pese ohun rere gbogbo fun ẹni ti n kọni.” (Gàlátíà 6:6)

Tani ki o ma pese ohun rere gbogbo fun ẹni ti o n kọ? Gbogbo awọn ti a ba n kọ ni ọrọ Ọlọrun ni! Eyi jasi pe, ko si ẹnikẹni ti a kọ ni ọrọ Ọlọrun ti o gbọdọ gbẹyin ninu ọrọ yi. Dipo bẹẹ, gbogbo wọn patapata ni o gbọdọ ma kopa ninu rẹ. Ṣe gbogbo awa ti a wa n kọ ni ọrọ Ọlọrun ni o ni agbara lati le kopa ninu fifun awọn ti o n kọ wa ni ọrọ rẹ lati ara awọn nkan ini wa? Bẹẹni, gbogbo awa ti a n kọ ni ọrọ Ọlọrun ni a ni agbara lati le ma gbe awọn ti o n kọ wa larugẹ pẹlu awọn nkan ini wa.

Lọna wo ni eyi gba ri bẹẹ? O ri bẹẹ nitoripe ireti Ọlọrun kọ ni pe pe ki a fun wọn ni ohun ti a ko ni bikoṣe pe ki a fifun wọn lati ara ohun ti a ni. Pọọlu, nigba ti o n ba awọn ara Kọrinti sọrọ lori bi a ti ṣe n fifunni lọna ti o tẹ Ọlọrun lọrun, sọ wipe, “Nitori bi imura tẹlẹ ba wa ṣaaju, o jasi itẹwọgba gẹgẹ bi ohun ti eniyan ba ni, ki i ṣe gẹgẹ bi ohun ti ko ni.” (2Kọ́rínntì 8:12) Njẹ o ri bayẹn? Imura (Iṣetan) wa lati gbọran si Ọlọrun lọrun ni ohun akọkọ ti O ma n fi oju si ninu ibaṣepọ wa pẹlu rẹ. Nitorina, niwọn igba ti a ba ti muratan lati gbọran si aṣẹ ti O pa pe ki a ma gbe awọn ti o n bọ wa pẹlu ọrọ rẹ larugẹ pẹlu awọn nkan ini wa, inu rẹ yoo dun si wa.

Amọ kiki ki a ṣetan lati fifun wọn nikan kọ ni ohun ti O n fẹ lati ọdọ wa; O tun n fẹ pe ki a fifun wọn lotitọ. Ko fẹ ki a ma sọ wipe, “Ọlọrun si ri ọkan pe mo fẹ fifun ọ o. O kan jẹ wipe n ko ni lọwọ ni.” Dipo eyi, nṣe ni O fẹ ki a ma fifun wọn ni ibamu pẹlu nkan ti a ni dipo ni ibamu pẹlu nkan ti a ko ni. Eyi jasi pe bi o ti wu ki nkan ini wa kere to, O si n reti pe ki a fifun wọn lati ara rẹ, ki a si ma ṣe aroye. Idi si ni pe niwọn igba ti o ba ti wa lati ọkan wa, ohun yowu ti a ba fifun wọn yoo jẹ itẹwọgba si i, ni ibamu pẹlu ohun ti a ni dipo ni ibamu pẹlu ohun ti a ko ni.

Wayi o, gbogbo wa naa ni a mọ wipe Ọlọrun mo ohun ti ẹnikọọkan wa ni. Nitorina, O mọ ohun ti ipa wa ka lati fi ran awọn ti o n bọ wa pẹlu ọrọ rẹ lọwọ, bi o ti wu ki nkan ini wa kere to. O wa ku si ọwọ wa lati gbọran si lẹnu, ki a si fifun wọn, tabi lati ṣe aigbọran si lẹnu, ki a si fi ohun yowu ti o yẹ ki a fifun wọn pamọ fun ara wa. Ṣugbọn ki a tun fi sọkan pe a ko le gan an tabi tan an jẹ lori ọrọ fifi funni. Ohun ti a ba gbin naa ni a o ka – a ko ni ka ohun ti a ko ba gbin. Eyi tunmọ si pe Ọlọrun ko ni pin wa lere fun ohun ti a ko ṣe fun un tabi fun awọn iranṣẹ rẹ. (Wo: Gàlátíà 6:7)

Ranti opo Sarefati. Ọlọrun mọ pe gbogbo nkan ti o ni nile rẹ ko ju ikunwọ iyẹfun kan ati ororo diẹ ninu kolobo lọ . Sibẹsibẹ O paṣẹ fun pe ki o pese ounjẹ fun iranṣẹ rẹ, Elija, lati ara rẹ. Wa kiyesi pe Ọlọrun ko ni ki o lọ ya owo lati se ounjẹ fun Elija tabi pe ki o duro di igba ti o ba di milionia ki o to fifun un. Dipo eyi, O sọ fun pe ki o fun ni ounjẹ lara kekere ti o ni ni asiko naa. Ki si ni idi? Idi ni pe niwọn igba ti o ba ti ṣetan lati gbọran si Ọlọrun lẹnu, diẹ kekere ti o fẹ fifun Elija lara kekere ti o ni yoo dun mọ ọn ninu, yoo si tun jẹ itẹwọgba lọwọ rẹ. (Wo: 1Awọn Ọba 17:8-24)

Awa dupẹ pe arabinrin yi gbọran si Ọlọrun lẹnu. Nitoripe o si gbọran si lẹnu, Ọlọrun pin lere pẹlu iṣẹ ara isọdọtun ojoojumọ ni gbogbo asiko ti iyan fi mu ni ilẹ naa. Lọna wo? O kan kiyesi wipe nṣe ni iyẹfun ati ororo rẹ n sọ ara wọn di ọtun ni ojoojumọ, debi wipe ko le ri wọn lo tan titi iyan naa fi pari. Eyi si jẹ nkan iyalẹnu gidigidi lati mọ.

Ti arabinrin yi ko ba wa gbọran si Ọlọrun lẹnu nkọ, lori awawi pe nkan ti o ni lọwọ kere? Ṣe a o ri oun ati ọmọ rẹ pamọ ni asiko iyan yi? Rara! Ki ni ko ba wa ṣẹlẹ si Elija? Ọlọrun ko ba tun wa ọna miran lati mojuto ni, bi O ti ma n ṣe tẹlẹ. Nitorina, Ọlọrun yoo tọju awọn ti O ba ran lati mojuto wa, yala a tọju wọn tabi a ko tọju wọn. Ṣugbọn a ko ni gba ere itọju ti a ko fun wọn lọwọ rẹ. Nitori eyi, ma ṣe gbẹyin ni fifi fun awọn ti o n bọ ọ pẹlu ọrọ Ọlọrun. Adura mi ni pe o ko ni padanu awọn iṣẹ ara ti o yẹ ki o waye ninu aye rẹ nipasẹ lilawọ rẹ si wọn, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Má ṣe gbẹ́yìn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwàrà 29, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 26 Read More »

Má tẹ̀bà ti ohun yówù tí kò bá kájúẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwàrà 22, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | 07045674587 Nọ́múbà: Vol. 12, No. 25

Olufẹ: Ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olurapada wa. Kaabọ si ọsẹ miran ninu oṣu Ọ̀wàrà 2023. Mo gbadura pe ki ọkan rẹ ma fi gbogbo igba gba okun lati ma ṣe tẹba ti ohunkohun ti o ba kere si nkan ti Ọlọrun fẹ ki o ni ati ki o gbadun laye yi, ni orukọ Jesu. Amin.

Ọkan lara awọn nkan ti a ri ninu Iwe mimọ ni pe Ọlọrun ko ki i fi tipatipa mu eniyan lati tẹwọgba ipese rẹ fun wọn ati lati gbadun rẹ. Ti a ko ba ni tẹwọgba oun ti O n naa si wa, O le ma ṣe ohunkohun lati ri daju pe a ri gba. Ti a ko ba si tun pinnu lati ma tẹba ti ohun yowu ti ko ba to ohun ti O fẹ ki a ni, O le ma ṣe nkankan lati ri wipe a ni ohun gbogbo ti O fẹ ki a ni.

Fun apẹrẹ, bi a ti fi han wa ninu bibeli, nigbati Ọba Jehoasi ti Isiraẹli lọ ki Wolii Eliṣa ki o to ku, o fi ara rẹ han bi ẹni ti ko ni itara to lati ni iriri irufẹ iṣẹgun ti o ga ti Ọlọrun fẹ ki o ni lori awọn ọta rẹ. Bi akọsilẹ naa ṣe lọ, Eliṣa sọ fun ọba yi lasiko yi pe ki o mu ọrun kan ati ọfa melokan lati ta. Ki si ni idi? Ṣe o fẹ ki o fi da oun laraya ni? Rara o! Dipo eyi, nkan ti o ni ki o ṣe yi jẹ nkan àmì ninu ẹmi. Bi Eliṣa ti ṣe jẹ ki o ye, awọn ọfa ti yoo taa yi jẹ ọfa Oluwa fun iṣẹgun lori awọn ara Aramu. (Wo: 2Àwọn Ọba 13:14-17)

Ki o to di asiko yi, awọn ara Aramu ti n pọn awọn ọmọ Isiraẹli loju gidigidi. Ọrọ naa si buru debi wipe a ko fi silẹ fun baba Jehoasi yi ti o ti jade laye ju aadọta ọkunrin ẹlẹṣin, kẹkẹ ogun mẹwa ati ẹgbẹrun mẹwa ọmọ ogun ẹlẹsẹ — gbogbo iyoku awọn ọmọ-ogun rẹ ni a ti parun patapata (2Àwọn Ọba 13:7). Nitorina, ti ilẹ naa yoo gba idande, ki a si tun fi idi rẹ mulẹ sinu iṣoriire bi tatẹyinwa, yoo nilo lati ni iṣẹgun leralera lori awọn ara Aramu yi ni iye igba ti o ba wu ki o jẹ.

Amọ eyi yoo nilo ki iyanu ṣẹlẹ. Ọlọrun yoo nilo lati da si ọrọ naa ati lati fun wọn ni iṣẹgun lera-lera ki wọn ba le bọ patapata kuro ninu ipọniloju awọn ara Aramu. Ki wa lo de ti ko gbe igbesẹ, ki O si fun wọn ni gbogbo iṣẹgun ti wọn nilo? Ṣe ọrọ wọn ko jẹ ẹ logun to lati ṣe bẹẹ ni? Abi ṣe dandan ni ki wọn kọkọ gbadura si ki O to fi han pe ọrọ wọn jẹ Oun logun ni?

Ni kukuru, lati dahun awọn ibere wọnyi, ọrọ awọn ọmọ Isiraẹli yi jẹ Ọlọrun logun nitootọ, O si tun fẹ tu wọn silẹ kuro lọwọ awọn ti o n niwọn lara. Bi a si ṣe ri ninu itan naa, ko tilẹ ṣetan lati duro de igba ti gbogbo wọn ba to korajọpọ lati gbadura si ki O to ṣe nkankan lori ọrọ wọn. Amọ ṣa o, ko fẹ ṣe ohunkohun lori ọrọ wọn lalai kọkọ jẹ ki wọn mọ pe Oun ni O n ṣiṣẹ. Aijẹbẹ, wọn le gbe oriyin ti o yẹ ki wọn gbe fun fun ara wọn tabi fun awọn oku oriṣa kan. Idi si ni yi ti O fi sọ fun Eliṣa lati kọkọ sọ fun ọba wọn nipa ohun ti O fẹ ṣe fun wọn ki o to bẹrẹ si ni ṣẹlẹ.

Nibakanna, awọn asiko kan ma n wa ti Ọlọrun le nilo lati fi awọn iran tabi ala kan han wa tabi ki O ran awọn wolii tabi angẹli kan si wa ki O to ṣe awọn nkankan fun wa. Idi si ni ki a ba le mọ wipe aṣeyọri, iwosan tabi aabo ti a n jẹgbadun ko ki i ṣe eyi ti o ti ara ṣababi tabi ohun ti a ṣiṣẹ tọ funra wa jade wa. Dipo eyi, o jẹ eyi ti o ti ara iṣẹ rere rẹ ninu aye wa jẹ jade.

Siwaju si, Ọlọrun fẹ ki ọba yi, Jehoasi, ri bi oun tikararẹ ṣe ni itara si lati bori awọn ọta rẹ ati lati fi idi orilẹ-ede rẹ mulẹ ninu alaafia ati iṣoriire. Nitorina, O sọ fun Eliṣa lati sọ fun pe ki o ta awọn ọfa iṣẹgun lori awọn ara Aramu ti o wa lọwọ rẹ. O wa ṣeni laanu pe, bi o tilẹ jẹ wipe ọkunrin yi mọ nkan ti o sọrọ mọ nkan ti o n ṣe, ọfa mẹta pere ni o ta ti o fi ṣiwọ. Eyi tunmọ si pe o tẹ ẹ lọrun lati bori awọn ara Aramu ni igba mẹta pere. (Wo: 2Àwọn Ọba 13:18)

Ṣe iṣẹgun igba mẹta pere wa to lati ba gbogbo ajaga ti a gbe le awọn ara Isiraẹli lori jẹ patapata? Rara! Eliṣa gan, ti ko ki i ṣe jagunjagun tabi oloṣelu, mọ wipe iṣẹgun ẹẹmẹta leralera lori awọn ara Aramu ko to lati fun wọn ni alaafia ni kikun. Wọn yoo nilo iṣẹgun leralera bi igba marun tabi mẹfa ki eyi to le waye. Ibanujẹ ni o wa jẹ wipe, fun awọn idi kan tabi omiran, olori ilẹ wọn, ẹni ti o tun jẹ aṣoju gbogbo wọn niwaju Ọlọrun, pinnu lọkan tirẹ pe iṣẹgun igba mẹta leralera ti to fun oun. Ọlọrun si fi aṣẹ si. Ko tilẹ wa sọ fun pe ki o lọ tun aṣiṣe rẹ ṣe. Nṣe ni O kan bu ọwọ lu nkan ti o yan.

Nibakanna, ti awa naa, yala nitori ẹru, imẹlẹ tabi ẹ̀mí-ìjákulẹ̀, ba lọ tẹwọgba ohunkohun ti o kere si nkan ti Ọlọrun fẹ ki a ni, O ṣeeṣe ki Oun naa fi ọrọ naa silẹ bẹẹ. Ṣugbọn laipẹ jọjọ ni yoo ye wa pe ohun yowu ti o ba kere si nkan ti Ọlọrun fẹ ki a ni ko le fi igba kankan to fun iriri alaafia, isinmi ati isesorere ti O fẹ ki a jẹgbadun laye. Nitorina, ninu ibaṣepọ rẹ pẹlu Ọlọrun, ma tun lailai lọ fun ohunkohun ti ko ba kaju nkan ti O fẹ ki o ni tabi ti o nilo mọ. Aijẹbẹ, o le fi gbogbo ayeraye rẹ kabamọ pe o ṣe bẹẹ.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Má tẹ̀bà ti ohun yówù tí kò bá kájúẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwàrà 22, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | 07045674587 Nọ́múbà: Vol. 12, No. 25 Read More »

Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ tàbí ìlawọ́ rẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwàrà 15, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 24

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ ṣi ọsẹ miran ninu oṣu Ọ̀wàrà 2023. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun pese fun gbogbo aini rẹ lọsẹ yi ati ni gbogbo eyi ti o ku ninu ọdun yi ni ibamu pẹlu ìlawọ́ rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi Iwe mimọ ti ṣe sọ, a le bere lọwọ Ọlọrun ohunkohun ti a ba nilo, ki a si reti pe ki O dawa lohun, niwọn igba ti a ba ti bere ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ (1Jòhánù 5:14). Amọ ṣa o, bi a tilẹ n gbadura ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ, a tun gbọdọ kọ láti má fi ireti idahun rẹ si adura wa sinu bi a ti ṣe n gbadura karakara to tabi sinu bi nkan ti a n bere lọwọ rẹ ti ṣe pọ to. Dipo eyi, nṣe ni ki a fi ireti idahun rẹ si adura wa sinu ilawọ rẹ.

Wo bi Pọọlu ti ṣe gbadura fun awọn ara Filipi ni ibamu pẹlu eyi: “Ṣugbọn Ọlọrun mi yoo pese ni kikun fun gbogbo aini yin, gẹgẹ bi ọrọ̀ rẹ ninu ogo ninu Kirisiti Jesu.” (Fílípì 4:19) Iwọ naa ro wo. Pọọlu ko bere pe ki Ọlọrun pese fun aini awọn ara yi ni ibamu pẹlu ohun ti wọn nilo tabi fẹ. Lafikun, ko sọ fun pe ki o pese fun aini wọn ni ibamu pẹlu laala wọn tabi ni ibamu pẹlu lilawọ wọn si awọn miran. Dipo eyi, o sọ fun pe ki o pese fun aini wọn ni ibamu pẹlu ọrọ̀ rẹ ninu Kirisiti Jesu.

Wayi o, lotitọ, Ọlọrun le pese fun aini awọn eniyan ni ibamu pẹlu ohun ti wọn nilo. Ṣugbọn ti O ba pese fun aini wọn nikan, ṣe awọn naa yoo le ran awọn miran lọwọ lọna ti o ni itumọ bi? Ko fẹrẹ jọ bẹẹ! Lafikun, Ọlọrun le pese fun aini awọn eniyan ni ibamu pẹlu laala wọn. Ṣugbọn ṣe oun ti yoo fun wọn nipasẹ laala wọn yoo to lati mojuto wọn ati awọn miran ti o yẹ ki wọn tọju? Ko fẹrẹ jọ bẹẹ!

Siwaju si, ti Ọlọrun ba tilẹ pinnu lati pese fun wa ni ibamu pẹlu bi a ti ṣe lawọ si, melo ninu wa ni yoo ri nkan ti o lojutu gba lọwọ rẹ? A ri lara wa awọn ti wọn n fi gbogbo igba ṣe ahun si Ọlọrun, awọn iranṣẹ rẹ ati awọn miran ni ayika wọn, bi o tilẹ jẹ wipe a ti gbọ oniruuru iwasu lori pataki ki a lawọ ki awọn ibukun Ọlọrun kan ba le ṣan bi omi lalai ni idiwọ ninu aye wa. Ti Ọlọrun ba wa wo eyi lati pese fun aini wa, ṣe nkan ti a o ma rigba lọwọ rẹ yoo to lati mu inu wa dun bi? Mi o ro bẹẹ.

Ọpọ loni ni inu wọn ko dun si Ọlọrun ati si awọn nkan ti O n fun wọn nitoripe wọn ro wipe nkan ti awọn lẹtọ si pọ ju nkan ti O n fun wọn lọ. Awọn wọnyi n woye nkan ti o fa ti awọn ti ko gbọn to wọn, ti ko ki i ṣiṣẹ karakara to wọn, ti ko ki i gbadura karakara to wọn ati boya ti ko tilẹ lawọ to wọn ṣe n rigba lọwọ Ọlọrun ju wọn lọ. Wọn wo pe eyi ko tọna. Nkan wọnyi si ti wa n pa ifarajin wọn fun un lara.

Njẹ Ọlọrun wa n ṣe aidara si wọn bi? Rara o! Ti o ba fẹ ki Ọlọrun pese fun ọ ni ibamu pẹlu iṣẹ ọwọ rẹ, adura gbigba rẹ ati ilawọ rẹ, yoo ṣe bẹẹ gẹgẹ, ayafi ti O ba kan fẹ ṣaanu fun ọ loku. Ti O ba si wa ṣe eyi, iwọ gan yoo ri wipe iṣẹ ọwọ rẹ ko to fun ọ lati jẹ igbadun awọn nkan ti o dara julọ ti O fẹ fun ọ. Ara awọn nkan ti Jesu Oluwa wa si kọ wa nipasẹ owe agbẹ kan ti o jade lọ lọjọ kan lati gba awọn alagbaro lati ṣiṣẹ ninu ọgba ajara rẹ ni eyi. (Wo: Mátíù 20:1-15)

Wayi o, bi itan naa ti ṣe lọ, awọn ẹni akọkọ ti ọkunrin agbẹ yi gba lọjọ ti a n wi yi sọ fun iye ti awọn fẹ ki o san fun wọn fun iṣẹ òòjọ́. O si gba. Ṣugbọn lẹyin igba ti wọn ti bẹrẹ si ni ṣiṣẹ, o ri wipe wọn ko pọ to lati pari iṣẹ ọjọ naa. Nitorina, o bẹrẹ si ni jade lọ titi di ọwọ irọlẹ ọjọ kanna yi lati mu awọn eniyan wa si lati ṣiṣẹ fun un. Ṣugbọn, ko ni adehun kankan pẹlu awọn ti o gba lẹyin eyi lori iye ti yoo san fun wọn. O kan sọ fun wọn pe oun yoo san nkan ti o ba tọ fun wọn ni.

Ni kukuru, nigba ti asiko to fun ọkunrin yi lati san owo ẹnikọọkan ti o ṣiṣẹ fun lọjọ naa, o sọ fun olori awọn oṣiṣẹ rẹ pe ko san iye kanna fun gbogbo wọn, bẹrẹ lati ori awọn ti a gba ṣiṣẹ kẹyin lọ si ori awọn ti a kọkọ gba ṣiṣẹ. Eyi si wa jẹ ki awọn ti o kọkọ gba ṣiṣẹ, ti wọn si ro wipe awọn yoo gba owo ju awọn yoku lọ, fi apa jánú pe ọkunrin yi i ko ṣe daradara. Ṣugbọn o sọ fun wọn pe ohun ko ṣe aidara si wọn rara bikoṣe pe oun san owo fun wọn ni ibamu pẹlu nkan ti wọn ṣe adehun lati gba lọwọ oun, ti oun si wa san owo fun awọn yoku ni ibamu pẹlu ilawọ oun.

Kini koko ọrọ? Oun naa ni pe bi o tilẹ ṣe pataki fun wa lati fi ara wa jin lati sin Ọlọrun, lati ma gbadura si i, lati lawọ si i ati si awọn miran ati lati ma ṣiṣẹ tọkantọkan, a ko gbọdọ lailai lepa lati gba ohunkohun lọwọ rẹ ni ibamu pẹlu awọn nkan ti a ṣe tabi ti a ti ṣe sẹyin. Dipo bẹẹ, nṣe ni ki a ma fi igba gbogbo lepa lati rigba lọwọ rẹ ni ibamu pẹlu ilawọ rẹ. Idi si ni pe kiki awọn nkan ti O ba pese fun wa ni ibamu pẹlu ilawọ rẹ ni yoo tẹ wa lọrun, ti yoo si tun mu inu wa dun. Mo si gbadura pe ki a ma fi igba gbogbo gba okun lati kọ otitọ yi ni kiakia ati lati bẹrẹ si ni fi ojoojumọ ṣe amulo rẹ ninu aye wa, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ tàbí ìlawọ́ rẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwàrà 15, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 24 Read More »

Má sọ ààyè rẹ nù

Ṣe àmúlò tí ó péye ipò wọn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwàrà 08, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 23

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ keji oṣu Ọwara 2023. Adura mi ni pe ki Ọlọrun la ọna fun ọ lati ri wọn gba ati lati jẹ igbadun wọn ohun gbogbo ti O fẹ ki o ni lọdun yi ti o ko i ti ni, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, ọkan lara awọn ọna lati ri awọn nkan ti Ọlọrun ti fun ọ gba ni kiakia tabi lati ni iriri igbala kuro ninu ipọniloju satani ni lati ṣe amulo ti o peye wiwa awọn adari ti O yan le ọ lori ninu ijọ rẹ. Bi a ti ṣe ri ninu iwe mimọ, ara awọn idi ti Ọlọrun ṣe fun wa ni awọn adari ninu awọn ijọ wa kaakiri ni ki wọn ba le ma ṣe ẹ̀ṣọ́ lori aye wọn, ki wọn si tun ma pese awọn ohun ti o ku diẹ kaato ninu igbagbọ wa nipa agbara Ẹmi Ọlọrun. Nitorina, a fun wọn ni aṣẹ lati sọ awọn ọrọ ti yoo yi aye wa pada titi lailai, lati gbadura si Ọlọrun fun wa ati lati gba idahun ati lati ba eṣu wi ati lati fooro iṣẹ rẹ ninu aye wa. (Wo: 2Kọ́ríntì 10:8; 1Tẹsalóníkà 3:10; Hébérù 13:17)
Amọ ṣa o, a gbọdọ kọ lati ṣe idamọ ipo ti wọn wa ninu aye wa ati lati ma ṣe amulo rẹ lọna ti o peye lati le jẹ igbadun iṣẹ iranṣẹ wọn lẹkunrẹrẹ. Fun apẹẹrẹ, a sọ fun wa ninu Iwe Mimọ bi obinrin opo kan ṣe sa tọ Wolii Eliṣa lọ fun iranwọ, ti o si ri gba. Bi akọsilẹ naa ti ṣe lọ, lẹyin igba ti ọkọ rẹ ku, ọkunrin kan ti o jẹ ni owo bẹrẹ si ni leri lati wa ko awọn ọmọkurin rẹ mejiji lọ gẹgẹ bi ẹrú. A ko wa sọ fun wa boya arabinrin yi kọkọ lọ ba awọn ẹbi tabi ọrẹ wọn lati ran wọn lọwọ kuro ninu iṣoro naa tabi ko lọ ba wọn. Ti o ba si jẹ wipe o lọ ba wọn, o ṣeeṣe pe wọn ko ni iranlọwọ kankan lati ṣe fun un. Ṣugbọn o ranti pe idile oun ni ibaṣepọ ti o loorin pẹlu Wolii Eliṣa. Wolii yi tilẹ mọ ọkọ rẹ daradara debi wipe o le fọwọ ṣọya lati sọ fun ẹnikẹni pe olododo eniyan ni. Nitorina, o sa tọ ọ lọ fun iranwọ. (2Àwọn Ọba 4:1)

Njẹ Eliṣa wa da arabinrin yi lohun nigba ti o lọ si ọdọ rẹ tabi ko da lohun? O da lohun. Lọna wo? Ṣe o fun ni owo ni? Rara o! Boya ko tilẹ ni owo ti o peye lọwọ lati fun lati yanju gbese ọkọ rẹ. Ṣugbọn o ni aṣe ti ẹmi ti o peye to lati bukun fun un ati lati sọ nkan ti o ni di ilọpo-ilọpo, ki o ba le san gbese rẹ, ki o si bọ kuro ninu iṣẹ. Eyiyi gan ni o si ṣe. O fun ni ọrọ Ibukun ti o yi aye rẹ pada titi lailai. (2Àwọn Ọba 4:2-7)

Ṣugbọn ṣe o mọ wipe ọkọ arabinrin yii naa ko ba ti ṣe amulo ibaṣepọ ti o ni pẹlu Eliṣa lati gba ọrọ ibukun ti yoo yanju gbese rẹ ki o to ku? Boya ti o ba ti ṣe eyi, ko ba ma ti ku iku aitọjọ ti o ku. Ko si ẹni ti o mọ. Ni kukuru, iyawo rẹ ṣe nkan ti ko ṣe, o si gba idile rẹ la kuro ninu iṣẹ atirandiran.

Nibakana, iwọ naa, nipa ṣiṣe amulo ti o peye aṣẹ ẹmi ti awọn adari ijọ rẹ, le gba okowo rẹ, igbeyawo rẹ tabi ẹbi rẹ la kuro lọwọ awọn iṣoro kan ti o ti kọ lati fi yin silẹ. Njẹ iwo yoo ṣe bẹ bi? Ṣe igberaga yoo jẹ ki o ṣe bẹ? Ṣe ojo yoo jẹ ki o ṣe bẹ? Ṣe ifarajiin rẹ fun igbe aye ikọkọ yoo rẹ yoo jẹ ki o ṣe bẹ?

Wo o, ọpọ awọn ọmọ Ọlọrun ni o n jiya ninu agọ ara wọn, ninu eto iṣunna wọn tabi ninu igbeyawo wọn nitoripe wọn ko ni ṣe amulo iṣẹ iranṣẹ awọn adari ijọ wọ. Awọn wọnyi si le ku sinu ijiya wọn, ti wọn ba kọ lati ṣe ohun ti o tọ. Wo nkan ti Jemisi sọ lori eyi: “Ẹnikẹni ṣe aisan ninu yin bi? Ki o pe awọn agba ijọ, ki wọn si gbadura sori rẹ, ki wọn fi ororo kun un ni orukọ Oluwa: Adura igbagbọ yoo si gba alaisan naa la, Oluwa yoo si gbe e dide; bi o ba si ṣe pe o ti dẹṣẹ, a o dari ji i.” (Jákọ́bù 5:14-15)

Njẹ o ri bayi? Ọmọ Ọlọrun kankan ti o ba n ṣe aisan ko ni lati ku sori ibusun aisan rẹ, bi o tile jẹ wipe ẹṣẹ ni o wa nidi aisan rẹ. O kan ni lati jẹ ki awọn adari ijọ rẹ gbadura fun ninu igbagbọ lasan ni. A o si wo o san, a o si tun dariji, ti o ba tilẹ ṣe. Ki ni idi? Idi ni pe a ti fun wọn ni aṣẹ lati gba iwosan ati idariji fun un nipasẹ igbagbọ ninu Kirisiti Jesu. Amọ ti ko ba wa ke si wọn fun adura nkọ? O ṣeeṣe ki o ku sinu aisan rẹ.

Wayi o, emi naa mọ pe ko ki i ṣe gbogbo awọn ti wọn pe ara wọn ni adari ijọ naa ni onigbagbọ eniyan ati ẹni ti o ṣe e gbẹkẹle lati ṣe oun ti o dara fun awọn ọmọ Ọlọrun ti o wa ni abẹ wọn. Amọ niwọn igba ti iwọ ba ti mọ pe awọn adari ijọ tirẹ jẹ onigbagbọ eniyan ati ẹni ti o ṣe fi ọkan tan lati ma fi igba gbogbo ṣiṣẹ fun rere rẹ, nṣe ni o yẹ ki o kọ lati ma ṣe amulo ti o peye aṣẹ ẹmi ti wọn ni fun iwosan, igbega ati igbala rẹ kuro lọwọ ikọlu ọta. Ki Ẹmi Ọlọrun si ma fi igba gbogbo kun ọkan rẹ pẹlu ọgbọn ati oye ti o peye lati ṣe bẹ ẹ gẹgẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Kí o ní ọ̀ṣẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ṣe àmúlò tí ó péye ipò wọn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwàrà 08, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 23 Read More »