December 2023

Ó ti lọ ṣíwájú rẹ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀pẹ 31, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 35

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọjọ Isinmi ti o kẹyin ọdun yi, eyi ti o tun jẹ ọjọ naa ti o pari ọdun yi. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun kun ọkan rẹ pẹlu ayọ ati alaafia ni gbogbo ọjọ naa ati bi a ti ṣe n sọda sinu ọdun tuntun, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe fẹ wọ inu ọdun tuntun lọ, mo fẹ gba ọ niyanju pẹlu diẹ lara awọn ọrọ Mose si awọn ọmọ Isiraẹli, iyẹn bi wọn ti ṣe fẹ kọja lọ sinu ilẹ ileri, ti o sọ wipe:

“Oluwa Ọlọrun rẹ funra rẹ ni yoo rekọja fun ọ. Yoo pa awọn orilẹ ede yii run niwaju u rẹ, iwọ yoo si mu ini ilẹ wọn, Josua naa yoo rekọja fun ọ, bi Oluwa ti sọ.” (Deutaronomi 31:3)

Tani yoo rẹkọja lọ siwaju awọn ọmọ Isiraẹli wọnyi si ori ilẹ ti wọn fẹ gba? Akọkọ, Oluwa Ọlọrun wọn funrarẹ ni yoo rekọja siwaju wọn lọ. Ki si ni idi? Oun naa ni lati mojuto ẹnikẹni tabi ohunkohun ti o le fẹ di wọn lọwọ lati wọ ilẹ naa ati lati gba a fun iṣoriire ati igbadun wọn. Nitorina, bi wọn ko tilẹ mọ gbogbo idojukọ ati anfaani ti wọn yoo ba pade ni ilẹ naa, wọn le fi igboya wọ inu rẹ, pẹlu imọ wipe Ọlọrun ti wa nibẹ ṣaaju wọn lati mojuto ohun gbogbo lati ṣiṣẹ fun rere wọn. Bi o si ṣe ri gẹlẹ naa niyẹn. Wọn fi igboya wọ ilẹ naa lọ, wọn si gba a, fun ogo Ọlọrun ati fun igbadun wọn.

Nibakanna, niwọn igba ti o jẹ wipe Ọlọrun kanna ti O lọ siwaju awọn ọmọ Isiraẹli yi lati gba ilẹ ti o n ṣan fun wara ati fun oyin fun wọn ni Ọlọrun ti awa naa, nṣe ni o yẹ ki a fi ọkan wa balẹ, pẹlu imọ wipe O ti rekọja siwaju wa sinu ọdun tuntun ti a fẹ wọ inu rẹ lọ fun wa. Ki si ni idi ti O ṣe rekọja sinu rẹ ṣiwaju wa? Oun naa ni lati ri pe ko si ohunkohun ti yoo di wa lọwọ lati gba ati lati jẹ igbadun ohun rere gbogbo ti O ti gbin sinu ọdun naa fun wa.

Nitorina, ẹ jẹ ki a gbe ibẹru yowu ti a le ni nipa ọdun tuntun ti a n wọ inu rẹ lọ ju silẹ, ki a si fi igboya wọ inu rẹ lọ. Idi si ni pe yoo jẹ ọdun ti o logo ju awọn ọdun tatẹyinwa lọ fun wa ati fun awọn ẹbi wa. Yoo jẹ ọdun ninu eyi ti Ọlọrun yoo jẹ ki ohun rere gbogbo ti O ti gbin sinu aye wa fun iṣoriire wa farahan. Bẹẹ si ni yoo jẹ ọdun ninu eyi ti yoo dari wa lati gba ati lati jẹ igbadun awọn nkan ti o dara julọ ti O ti gbin si ilẹ wa fun wa. A kan nilo lati fi ọwọ sowọpọ pẹlu rẹ ni. O si di dandan ki a jẹgbadun ohun gbogbo ti O ni ni ipamọ fun wa.

Siwaju si, gẹgẹ bi Mose ti ṣe fi han awọn ọmọ Isiraẹli yẹn, ẹnikan naa tun wa ti yoo rekọja siwaju wọn lọ si inu ilẹ ileri naa. Ẹni naa ni Joṣua. Ta wa ni Joṣua? Joṣua ni ẹni naa ti Ọlọrun yan, ti O si tun ṣe yẹ lati dari wọn lati gba ilẹ naa ti O fẹ fun wọn. Eyi tunmọ si pe oun ni aṣoju tabi iranṣẹ Ọlọrun ti a yan lati ran gbogbo wọn lọwọ titi wọn yo fi fi ẹṣẹ mulẹ ni ilẹ naa. Ṣe o wa ṣe iṣẹ rẹ daradara tabi ko ṣe e? O ṣe daradara. O dari wọn, O si tun jagun-ṣẹgun pẹlu wọn titi ọkọọkan ninu wọn fi gba ini tirẹ, ti o si bẹrẹ si ni gbe ibẹ.

Nibakanna, mo fẹ ki o mọ pe Ọlọrun ti yan, O si tun ti ran awọn oluranlọwọ ṣiwaju wa lọ sinu ọdun tuntun ti a n wọ inu rẹ lọ. Ki ni idi? Idi naa ni ki wọn ba le ba wa ṣiṣẹ, ki wọn si tun ran wọn lọwọ titi gbogbo ete rẹ ni rere fun aye wa yoo fi wa si imuṣẹ. A kan nilo lati da ọkọọkan awọn oluranlọwọ yi mọ, ki a si tun fi irẹlẹ fi aye gba wọn lati ṣe ohun ti Ọlọrun fẹ ki wọn ṣe ninu aye wa ati fun aye wa. Ṣiṣe iṣẹ wọn, lotitọ, ṣeeṣe ki o ti wa kuro nibi ti a joko tẹtẹrẹ si. Ṣugbọn ti a ba fọwọsowọpọ pẹlu wọn, ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun, wiwa wọn ninu aye wọn di dandan ki o yọri si ifarahan ogo Ọlọrun ninu ọdun naa.

Nitorina, fi oju ṣọna fun ọdun tuntun alarinrin, bi o ti wu ki nkan ri fun ọ lọwọlọwọ yi. Adura mi ni pe ki a fun ọkan rẹ ni okun lati fọwọsowọpọ pẹlu Ọlọrun ati pẹlu gbogbo awọn ti O le e fẹ lo fun ọ ninu ọdun naa, ni orukọ Jesu. Amin.

A kú ìmúra ọdún tuntun.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ó ti lọ ṣíwájú rẹ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀pẹ 31, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 35 Read More »

Ìmọrírì Ọlọ́run àti ènìyàn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀pẹ 24, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 34

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o kẹyin ọdun 2023. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun ṣe ohun gbogbo ti o ni ṣe pẹlu rẹ ni aṣepe, ki O si tun kun ọkan rẹ ati ile rẹ pẹlu ayọ ati alaafia ninu ọsẹ naa, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ṣe n wọ awọn ọjọ ti o kẹyin ọdun yi, o ṣe pataki ki o fi tinutinu fi imọriri han si Ọlọrun ati si gbogbo awọn ti O ti lo fun igbega, itura ati aabo rẹ ninu ọdun naa. Ki ni idi ti eyi ṣe ṣe pataki? Akọkọ, idi ni pe ifẹ Ọlọrun ni fun wa lati ma fi gbogbo igba mọ riri rẹ fun ohun ti O n ṣe fun wa ati lati mọ riri awọn ti O n lo fun wa ni ọna kan tabi omiran.

Fun apẹrẹ, Pọọlu sọ eyi fun wa nipa mimọ riri Ọlọrun: “Ẹ maa dupẹ nigba gbogbo ipokipo ti o wu ki ẹ wa; nitoti pe, eyi ni ifẹ Ọlọrun fun yin ninu Kirisiti Jesu nitootọ.” (1Tẹsalóníkà 5:18) Njẹ o ri bayẹn? Ifẹ Ọlọrun ni fun wa lati ma fi ọpẹ fun un ni ipokipo ti a ba. Bawo si ni a ṣe le ṣe eyi? A le ṣe e nipa ruru ẹbọ iyin si I (Hébérù 13:15). A si tun le ṣe e nipa fifi fun un lati ara nkan ini wa (Ìwé Òwe 3:9).

Siwaju si, Pọọlu so eyi fun wa nipa mimo riri awọn ti o n dari wa ninu awọn ijọ wa: “Awọn alagba ti o ṣe akoso daradara ni ki a ka yẹ si ọla ilọpo meji, pẹlu pẹlu awọn ti o ṣe laalaa ni ọrọ ati ni kikọni.” (1Tímótì 5:17) Njẹ o ri bayẹn? Awọn ti o n bọ wa pẹlu ọrọ rẹ yẹ fun ọla ilọpo meji. Eyi jasi pe wọn yẹ ni ẹni ti o yẹ ki a mo riri rẹ pẹlu ọrọ ẹnu wa ati pẹlu awọn nkan ini wa. Idi si ni pe nkan ti wọn n ṣe n mu aye wa tẹsiwaju, o si tun n pa ọkan wa mọ.

Amọ ṣa o, ko ki i ṣe kiki awọn ti o n bọ wa pẹlu ọrọ Ọlọrun nikan ni ọlọ ilọpo meji tọ si. Awọn miran ti Ọlọrun tun ti lo ni ọna ara ọtọ lati mu aye wa ni itẹsiwaju tabi lati pa wọn mọ ninu ọdun yi naa yẹ ni ẹni ti a n bu ọla ilọpo meji fun. Ọrọ ti wọn naa kọja ki a kan fi ẹnu bu ọla fun wọn; o tun yẹ ki ẹbun diẹ ti ọdọ wa jade si wọn. Eyi ko si ni i ṣe pẹlu ki a ra ẹbun olowo nla fun wọn, bi ko tilẹ si ohun ti o buru ninu ki a ṣe eyi ti owo rẹ ba wa. Dipo bẹẹ, o ni i ṣe pẹlu ki a ba wọn lo pẹlu ọkan imọriri otitọ.

Wayi o, ti a ba wa kọ lati fi otitọ inu ati tọkantọkan mọ riri Ọlọrun ati awọn ti O ti lo lati bukun fun wa ni awọn ọna ti o farahan, akọkọ, nṣe ni a n ti ilẹkun lati ri gba si lọwọ wọn mọ ara wa. Yatọ si iyẹn, o ṣeeṣe ki a tipasẹ eyi ṣi ilẹkun aye wa silẹ fun idajọ Ọlọrun. Fun apẹrẹ, nigba ti Nabali kọ lati mọ riri Dafidi ati awọn eniyan rẹ fun ohun ti Ọlọrun lo wọn lati ṣe fun awọn eniyan rẹ, Ọlọrun da si ọrọ naa lati ṣe idajọ rẹ. Eyi si yọri si iku aitọjọ fun un. (Wo: 1Sámúẹ́lì 25)

Siwaju si, Jesu sọ owe ti o da lori okunrin ọlọrọ kan ti ilẹ rẹ so eso ọpọlọpọ ati bi ọkunrin naa ko ṣe ronu rara lati dupẹ lọwọ Ọlọrun tabi lati bu ọla fun pẹlu ohunkohun lati ara ere rẹ. Gbogbo ọrọ rẹ ko kọja bi yoo ṣe jẹgbadun aye si ati bi yoo ti ṣe fẹ awọn ibi ti o n ko eso ilẹ rẹ si. Nitorina, Ọlọrun ṣe idajọ rẹ gẹgẹ bi ahun, O si mu ẹmi rẹ kuro ni asiko iṣoriire rẹ. Oluwa wa wa pari owe yi nipa sisọ wipe bayi gẹlẹ ni yoo ti ṣe ri fun olukuluku ẹni naa ti o n to ọrọ jọ fun ara rẹ ṣugbọn ti ko lawọ si Ọlọrun. (Wo: Lúùkù 12:16-21)

Adura mi wa ni pe idajọ Ọlọrun ko ni wa si ori rẹ nitori ikuna rẹ lati mọ riri rẹ ati lati mọ riri awọn miran ti imọriri tọ si lati ọdọ rẹ ni ọna ti o peye. Ṣugbọn iwọ naa wa gbọdọ ronu jiinlẹ lori awọn nkan ti O ti ṣe fun ọ ni ọdun yi ati lori ọna ti o o gba mọ riri rẹ. Yatọ si eyi, tun ronu jinlẹ lori gbogbo awọn ti O ti lo fun iṣoriire ati ibalẹ-ọkan rẹ lọdun yi ati ọna ti o o gba mọ riri wọn, paapaa-julọ ni asiko ọdun yi. Mo si gbadura pe ki a tọ ọkan rẹ lati ṣe ohun ti o tọ lori awọn nkan wọnyi, ki a si tun kun apo rẹ pẹlu ohun gbogbo ti o nilo lati ṣe bẹẹ gẹgẹ. Amin.

Ku ifojusọna fun ọdun Keresimesi!

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ìmọrírì Ọlọ́run àti ènìyàn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀pẹ 24, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 34 Read More »

Má ṣe jẹ́ ẹlẹ́gàn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀pẹ 17, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 33

Olufẹ: Ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ọ̀pẹ 2023. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun mu ki inu iwọ ati ile rẹ dun lotitọ ati ni gbogbo ọna ninu ọsẹ tuntun yi ati ni gbogbo eyi ti o ku ninu ọdun yi. Amin.

Wayi o, ọkan lara awọn ọna lati ma fi igba gbogbo ni iriri idunnu otitọ lati ọwọ Ọlọrun ni ki a ma fi gbogbo igba bọwọ fun ohunkohun ti O ba sọ fun wa, bi O tilẹ jẹ pe ohun ti O sọ ko mọgbọn wa loju wa. Bibeli sọ wipe omugọ Ọlọrun gbọn ju ọgbọn eniyan lọ ati wipe ailera rẹ ni agbara ju agbara eniyan lọ (1Kọ́ríntì 1:25). Nitorina, bi ọkan wa ko ba tilẹ le gbe nkan ti O n sọ fun wa nipa ara rẹ tabi nipa aye wa, nkan ti yoo jẹ iwa ọgbọn fun wa ni ki a tẹwọ gba a, ki a si gbe igbesẹ ni ibamu pẹlu rẹ.

O wa ṣeni laanu pe, nitori ailoye nkan wọnyi, ọpọ ni o ma bu ẹnu atẹ lu ohunkohun ti Ọlọrun ba sọ fun wọn ti ọpọlọ wọn ko ba le e gbe. Nitorina, wọn ko le ri ere igbọran si ọrọ rẹ jẹ. Yatọ si iyẹn, wọn tilẹ tun le padanu aye wọn tabi awọn nkan miran ti o ṣe pataki si wọn nitori ikẹgan wọn.

Fun apẹrẹ, ninu iwe Awọn ọba keji, ọri ikẹfa ati ikeje, a ri itan iransẹ ọba Isiraẹli kan ti o kẹgan ọrọ Oluwa ati nkan ti o ṣẹlẹ si nitori ikẹgan rẹ. Bi akọsilẹ naa ti lọ, iyan buruku kan ti o n ti awọn eniyan lati ma pa awọn ọmọ ara wọn jẹ ni o mu ni ilẹ Isiraẹli. Ni asiko ti awọn eniyan wa bẹrẹ si ni pa awọn ọmọ wọn jẹ yi ni oba ṣẹṣẹ wa ranti pe Wolii Eliṣa ma wa ni ilẹ naa ati wipe agba rẹ ko yẹ ki o wa ni ọja, ki ori ọmọ tuntun si ma ti oju rẹ wọ. Eyi si wa farapẹ iha ti awọn adari ijọba wa, paapaa-julọ ni orilẹ-ede wa, ma n kọ si nkan. Awọn adari ti wọn ma n duro ki nkan kọkọ bajẹ naa ki wọn to gbe igbesẹ lori rẹ ni. Nitorina, ti ko ba ṣe wipe iṣoro ọpọ eniyan ba da iṣoro wọn, ti ko ba jẹ wipe iṣoro ọpọ ba balẹ si ẹnu ọna wọn, wọn ko ni kọ iha ti o nitunmọ kankan si ibalẹ-ọkan awọn eniyan wọn.

Ni kukuru, nigba ti ọba yi pada taji kuro loju oorun rẹ, o ran oniṣẹ si Wolii Eliṣa, Ọlọrun si gba ẹnu wolii naa sọrọ si ilẹ naa, wipe, “Gbọ ọrọ OLUWA. Eyi ni ohun ti OLUWA sọ: Ni asiko yii ni ọla, a o ta oṣuwọn iyẹfun kikuna kan ni ṣekeli kan ati meji oṣuwọn ọka fun ṣekeli kan ni ẹnu bode Samaria.” (2Àwọn Ọba 7:1) Ti a ba fi oṣuwọn ti ode oni wo o, ṣekeli kan n lọ si bi igba naira o le mejila nigba ti oṣuwọn iyẹfun kan yoo si fẹrẹ gba to lítà omi meje ati aabọ. Nitorina, nṣe ni o dabi ki a sọ pe oṣuwọn (kongo) meji iyẹfun ko ni ju igba naira le ni aadọta lọ.

Njẹ iyẹn ko wa dabi àsé ati nkan ti ko le lailai ṣeeṣe leti? O da bẹẹ! Ṣugbọn ni asiko ti a n sọ yi, Ọlọrun sọrọ nipasẹ wolii rẹ, Eliṣa, wipe Oun yoo mu iṣẹlẹ kan waye ni aarin ọjọ kan ti yoo jẹ ki owo ounjẹ walẹ ni Samaria to bẹẹ gẹẹ ti ebi yoo fi poora ninu ilu naa. Boya ọba yii wa gba ọrọ yi gbọ tabi ko gba a gbọ, a ko le sọ. Idi si ni pe ko sọ nkankan le lori. Nṣe ni o kan ṣaa da a le, ti o si n woye bi ọrọ ti Ọlọrun sọ yoo ti ṣe wa si imuṣẹ.

Ṣugbọn a wa ri iransẹ kan ti o sunmọ ọba yi pẹkipẹki ti o ri ara rẹ bi ẹni ti o gbọdọ bu ẹnu atẹ lu nkan ti Oluwa sọ. Kini idi? O ro wipe ọrọ ti ko mọgbọn wa ni. Ni iwoye tirẹ, ti a ba tilẹ ṣi ferese ọrun silẹ, ti ounjẹ si bẹrẹ si ni rọ jade lati ibẹ bi ojo, nkan ti Ọlọrun sọ yi ko le e waye. Ki idi ti o fi sọrọ bi eyi? O sọrọ bi eyi nitoripe nkan ti Oluwa sọ silẹ yi ko ni itunmọ kankan ti awọn ti o mọ nipa eto iṣuna le tẹwọgba. Nitorina, o sọ ọ di ọrọ yẹyẹ. Nitoripe o si sọ ọ di ọrọ yẹyẹ, Oluwa ṣe idajọ ikẹgan rẹ lati ipasẹ Eliṣa. A sọ fun wipe a o jẹ ki oju rẹ ri ohun daradara ti Ọlọrun ti ṣeto lati ṣe fun awọn eniyan rẹ, ṣugbọn a ko ni gba ẹnu rẹ laaye lati tọ ọ wo. Bẹẹ gẹgẹ ni nkan si ṣe ri fun. (Wo: 2Àwọn Ọba)

Wayi o, ni aarin ọjọ melokan yii, mo ti ba awọn eniyan takurọsọ ti wọn gbagbọ pe ko si ohun ti Ọlọrun le ṣe fun orilẹ-ede wa ti o le jẹ ki nkan pada si bi wọn ti ṣe ri ni ọpọ ọdun sẹyin. Eyi jasi pe irufẹ awọn wọnyi, bi wọn tilẹ jẹ Kirisitiẹni, ko gbagbọ ninu adura ti a n gba fun orilẹ-ede wa. Iyẹn ni idi fun ikẹgan wọn. Amọ, a ti ri wipe nkan ti o lewu ni lati kẹgan ọrọ Oluwa, yala ọrọ ti O sọ nipa ara rẹ, nipa wa, nipa awọn miran tabi nipa ohunkohun. Ti o ko ba tilẹ gba ohun ti O sọ gbọ, jẹ ki aigbagbọ rẹ mọ ni ọdọ rẹ. Ma ṣe jẹ ki o tan kalẹ de ọdọ awọn miran tabi ki o ma fi ọrọ rẹ ṣẹ̀fẹ̀. Idi ni pe awọn ti o n fi ọrọ Ọlọrun ṣẹfẹ n fi ara wọn si abẹ idajọ rẹ laimọ (Sáàmù 1:1; 2Pétérù 3:3-9). Ti iru wọn ba wa lọ pade eniyan bi Wolii Elija tabi Apọsiteli Peteru, ti yoo mu ki idajọ yi wa si imuṣẹ lori wọn, wọn le ma gbe ile-aye royin ohun ti o ṣẹlẹ. Nitorina, ṣọ ara rẹ. Njẹ ki Oluwa rere ma fi igba gbogbo jẹ ki ọkan rẹ wa ni irẹlẹ niwaju rẹ. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Má ṣe jẹ́ ẹlẹ́gàn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀pẹ 17, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 33 Read More »

Àyẹ́sí tí ó kọjá bẹ́ẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀pẹ 10, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 32

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu ti o kẹyin ọdun yi, oṣu Ọ̀pẹ 2023. Adura mi ni pe ki Ọlọrun dari rẹ lati ṣe ohun rere gbogbo ti o yẹ ki o ṣe lọdun yi, ki awọn èrè rẹ ti o yẹ ki o jẹ tirẹ naa ba a le jẹ tirẹ lálàì si idaduro, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, niwọn ọjọ diẹ ki a to kan Jesu mọ agbelebu, a ṣeto apejẹ kan lati fi yẹ ẹ si ni Bẹtani, iyẹn ni ibi ti o gbe ji Laṣaru dide kuro ninu oku. Maria, arabinrin Laṣaru, si ṣe amulo asiko yi lati yẹ ẹ si ni ọna ti ko si ẹni ti o reti ati ni ọna ti o kọja bẹ ẹ. Ki wa ni o ṣe? Akọsilẹ rẹ ni yiL

“Nigba naa ni Maria mu ororo ikunra nadi, osuwọn lita kan, ailabula, olowo iyebiye, o si n fi kun Jesu ni ẹṣẹ, o si n fi irun ori rẹ nu ẹsẹ rẹ nu. Ile si kun fu oorun ikunra naa. Nigba naa ni ọkan ninu awọn ọmọ-ẹyin rẹ, Judasi Iskariotu, ọmọ Simoni ẹni ti yoo fi I han, wi pe, “Eeṣe ti a ko ta ororo ikunra yii ni ọọdunrin owo idẹ ki a si fi fun awọn talaka?” Ṣugbọn o wi eyi, ki i ṣe nitori ti o naani awọn talaka; ṣugbọn nitori ti o jẹ ole, oun ni o ni apo, a si maa ji ohun ti a fi sinu rẹ lati fi ran ara rẹ lọwọ. Nigba naa ni Jesu wi pe, “Ẹ fi i ṣilẹ, o ṣe e silẹ de ọjọ isinku mi. Nigba gbogbo ni ẹyin sa a ni talaka pẹlu yinl; ṣugbọn emi ni ẹ ko ni nigba gbogbo.” (Jòhánù 12:3-8)

Njẹ o ri bayẹn? Lati yẹ Jesu si, arabinrin yi da odidi igo ororo ikunra kan ti o to owó ọ̀yà ọdun kan alagbaṣe si ni ẹṣẹ. Igba wo ni o bẹrẹ si ni gbero nkan yi? A ko mọ. Bawo si ni o ti ṣe ri irufẹ igo kan ororo ikunra olowo iyebiye yi? A ko mọ. Ṣugbọn a mọ wipe nkan ti o ṣe ni ọjọ ti a n wi yi ko jẹ itẹwọgba si ọpọ awọn ti o ri i. Kini idi? O kọja bẹ ẹ!

Ki a sọ otitọ, o kọja bẹ ki a fi owo oṣu ọdun kan ra igo ororo ikunra kan, ki a si tun wa fi gbogbo ororo ikunra naa ṣofo sori atẹlẹsẹ ẹnikan laarin iṣẹju melokan. Ọpọ ni yoo tilẹ ka si iwa apa lati lo irufẹ ororo ikunra yi tan ni arin oṣu melokan. Ṣugbọn Maria ko lo o tan ni aarin oṣu melokan bikoṣe ni aarin iṣẹju melokan. O si ṣe eyi lalai tilẹ bikita tabi lọra. O ṣe e tayọtayọ, o si tun n fi irun ori rẹ nu atẹlẹsẹ Oluwa, bi o ti n tu ororo ikunra naa si ori wọn.

Ki wa lo fa ti o fi ṣe bẹ ẹ? Idi ti o fi ṣe eyi kọja nkan ti a tilẹ le ro. Amọ daju-ṣaka ni pe Jesu tobi lọwọ rẹ debi wipe o fẹ ṣe ayẹsi rẹ lọna ti o fi ma jẹ wipe ẹnikẹni ti o ba gbọ nkan ti o ṣe di dandan ki o sọ wipe, “Emi wa leyun un? Eyun un ko wa pọju bi?” Nkan ti o si ṣẹlẹ gẹlẹ ni eyi. Gbogbo awọn ti o ri nkan ti o ṣe ni o n kọ ha, pe, “O to gẹ ẹ! Ki ni oun n ṣe? Eyi o wa pọju?” Judasi Isikarioti tilẹ gboju agan si, ti o si ọ wipe nṣe ni ko ba ti fun Oluwa ni ororo ikunra naa, ki awọn ba a le ta a, ki wọn si fun awọn talaka ni owo rẹ.

Amọ ṣa o, si iyalẹnu gbogbo wọn, Oluwa ko da Maria lẹkun tabi ba a wi fun nkan ti o ṣe. Dipo bẹ ẹ, nṣe ni O sọ wipe o ṣe nkan ti o ṣe nipasẹ idari Ẹmi ni. O tilẹ fi kun un pe Ọlọrun gangan ni O jẹ ki o fi ororo ikunra naa pamọ di asiko naa, lati pese rẹ fun isinkun rẹ. Eyi jasi pe, ti ko ba lọ ṣe ayẹsi rẹ ni ọna ti o gba ṣe e ni ọjọ naa ni, anfaani lati ṣe e ko ba fo o ru titi lailai ni, nitoripe ni asiko yi kanna ni a mu un, ti a si pa a. Ṣugbọn nitoripe o ṣe e, gẹgẹ bi Matiu ati Maaku ti ṣe kọ silẹ ninu awọn iwe iyinrere wọn, Oluwa sọ wipe nibikibi ti wọn ba n ti polongo iyinrere ni wọn yoo ti ma sọ ohun ti o ṣe n iranti rẹ. Eyi ni mo si n ṣe nibiyi. (Wo: Mátíù 26:13; Máàkù 14:9)

Ni kukuru, ki ni koko itan yi? Koko akọkọ ni pe o yẹ ki a ma ni erongba lati ṣe ayẹsi Jesu ni ọna ti o kọja bẹ ẹ, ni ọna ti yoo jẹ ki awọn ti o wa ni ayika wa ma fẹ woye pe boya awa nikan ni O dara si ni. Idi si ni pe o tọ si i. Koko ekeji ni pe o yẹ ki a kọ bi a ti ṣe n gbadura si Ọlọrun lati ma dari wa lati ṣe idamọ gbogbo anfaani lati yẹ Oluwa si ti ko yẹ ki a padanu laye yi ati lati jẹ ki a ma wa ni imurasilẹ lati lo awọn anfaani naa. Aijẹbẹ, a o padanu awọn ere ara-ọtọ ti o yẹ ki o jẹ tiwa nikan.

Wayi o, boya Ẹmi Ọlọrun ti n sọ fun ọ pe opin-ọdun yi n fun ọ ni anfaani lati ṣe nkan àrà-ọ̀tà, nkan ti o kọja afẹnusọ lati yẹ Oluwa si. Yoo jẹ igbesẹ ọlọgbọn fun ọ lati gbọ nkan ti O n sọ ati lati ṣe ni kankan. Aijẹbẹ, anfani lati ṣe bẹ ẹ le ma yọju mọ lailai. Ti eyi ba si wa ṣẹlẹ, a jẹ wipe ere ti o yẹ ki o jẹ tirẹ naa ko ni yọju lailai. Adura mi ni pe gẹgẹ bi Maria, Ọba Solomọni ati Banaba ko ti ṣe padanu anfani ti wọn ni lati yẹ Ọlọrun si lọna ti o kọja afẹnusọ, ti wọn si gba ere ti ko wọpọ lati ọwọ rẹ, iwọ naa ko ni padanu tirẹ. Amin. (Wo: 1Àwọn Ọba 3:4-15; Ìṣe Àpọ́sítélì 4:36-37)

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Àyẹ́sí tí ó kọjá bẹ́ẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀pẹ 10, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 32 Read More »

Ìbá má ṣe pé Olúwa wà níhà wá | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀pẹ 26, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 31

Olufẹ: ki oore–ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsu ti o kẹyin ọdun yi, iyẹn oṣu Ọ̀pẹ. Adura mi si ni pe ki oṣu naa jẹ eyi ti ayọ iwọ ati ile rẹ yoo kun akunwọsilẹ ninu rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

O yẹ ki a fi ọpẹ fun Ọlọrun fun bi O ti ṣe fun wa ni anfaani lati ri oṣu ti o kẹyin ọdun yi. Nitootọ, ọdun yi jẹ eyi ti o le gidigidi fun orilẹ-ede wa lapaapọ. O si ṣeeṣe ki o jẹ eyi ti o le gidigidi fun iwọ ati idile rẹ naa. Sibẹsibẹ, Ọlọrun ko jẹ ki gbogbo awọn iṣoro odun naa gbe wa mi. O si yẹ ki a dupẹ lọwọ rẹ fun eyi.

Wayi o, Saamu Dafidi kan wa ti mo woye pe o tọ fun wa lati ka ati lati ṣe asaro le lori ni irufẹ asiko yi. Eyi ni Saamu 124, ti o si ka bayi:

“iba ma ṣe pe Oluwa ti o ti wa ni tiwa, ni ki Isiraẹli maa wi nisinsinyi; Iba ma a ṣe pe Oluwa ti o ti wa fun wa, nigba ti awọn eniyan dide si wa: Nigba naa ni wọn iba gbe wa mi laaye, nigba ti ibinu wọn ni ru si wa: Nigba naa ni omi wọn-ọn-ni iba bo wa mọlẹ, iṣan mi iba ti bori ọkan wa: Nigba naa ni agberaga omi iba bori ọkan wa. Olubunkun ni Oluwa, ti ko fi wa fun wọn bi ohun ọdẹ fun ẹyin wọn. Ọkan wa yọ bi ẹyẹ jade kuro ninu okun apẹyẹ: okun ja, awa si yọ. Iranlọwọ wa n bẹ ninu orukọ Oluwa, ti o da ọrun oun aye.” (Saamu 124)

Njẹ o ri bayẹn? Nkan ti o yẹ ki a ma sọ ni asiko yi pe idi ti awa ati awọn ti a nifẹ wọn ko ṣe ti lugbadi ibinu, ilara ati iwa ika awọn ọta ti o yiwa ka ninu ọdun yi ni pe Ọlọrun wa niha tiwa. Ti ko ba ṣe pe O wa ni iha wa ni, a ko ba ti lu igbadi erongba wọn ni ibi si wa. Eyi si ni o yẹ ki ẹri mi jẹ ni asiko yi. Oun si ni o yẹ ki ẹri ti iwọ naa jẹ ni asiko yi.

Lafikun, idi ti awọn idojukọ ti o dabi ikun omi ati omi ti o n binu ti o ti kọju ija si orilẹ-ede yi ati si iwọ naa pẹlu lọdun yi ko ṣe ti gba ọ lọ ni pe Ọlọrun wa ni iha tirẹ. Ti Ọlọrun ko ba si ni iha rẹ ni, o ṣeeṣe ki o ti di itan loni. Ṣugbọn nitori pe O n fi gbogbo igba wa pẹlu rẹ, o wa laye, o si tun wa ni ààyè tobẹ gẹẹ ti o fi le sọrọ nipa awọn nkan ti o ti la kọja. Ṣe ko wa yẹ ki o ma yin orukọ rẹ fun eyi? O yẹ.

Siwaju si, o ṣeeṣe ki o ti ba ara rẹ ni awọn ipo kan ninu ọdun yi ninu eyi ti o ti dabi ẹni pe Satani ti papa mu ọ, awọn ipo ti o ti ro wipe ko si ọna abayọ fun ọ kuro lọwọ idojuti, ìṣẹ́ tabi iku ti o n fẹju mọ ọ. Sibẹsibẹ, lọna kan tabi omiran, ikẹkun ti o mu ọ ja, o si bọ lalai fi ara pa. Tani o ro wipe o jẹ ki eyi ṣeeṣe? Ọlọrun ni. Oun ni O jẹ ki o bọ bi ẹyẹ ti ṣe n bọ ninu ikẹkun pẹyẹpẹyẹ. Oun ni ko jẹ ki o di ounjẹ fun eṣu ati awọn iranṣẹ rẹ.

Nitorina, bi o ti wu ki nkan ti o ti la kọja lọdun ti ṣe le ri, o yẹ ki o fi imore atọkanwa, eyi ti ko si lẹtan, han si Ọlọrun fun bi O ti ṣe pa ọ ma lati ri ọsu ti o kẹyin ọdun yi. Lotitọ, nkan le ma dara to bi o ti ṣe fẹ ki wọn ri ni aye rẹ ni asiko yi. O tilẹ ṣeeṣe pe awọn nkan kan ti o dara tẹlẹ ninu aye rẹ ti bajẹ, ki awọn nkan miran ti o si ti bajẹ tẹlẹ tun ti buru si. Amọ ṣa o, lakọkọ, o nílò lati ye ọ pe idi ti o ti tilẹ ṣe ri ohun daradara kankan gbeṣe tabi gbadun lọdun yi ni Ọlọrun. Lalai si rẹ, iba ma ti ṣeeṣe fun ọ lati ṣe ohunkohun, ri ohunkohun gba, ri ohunkohun jẹ tabi ri ohunkohun jẹgbadun rara ninu ọdun yi. (Wo: Oníwàásù 2:24-25; Àìsáyà 26:12; 1Tímótì 6:17)

Yatọ si iyẹn, nkan miran ti o tun ni lati yé ọ ni pe niwọn igba ti ẹmi ba si wa ninu rẹ, o si le ri didara Oluwa ni ilẹ alaaye, ti o ba le ri daju pe o ko dẹkun lati ma fi igbẹkẹle rẹ sinu rẹ ati lati ma dupẹ lọwọ rẹ. Dafidi, ninu Saamu rẹ miran, sọ wipe, “Ṣugbọn emi ti gbagbọ lati ri ire Oluwa ni ilẹ alaaye.” (Saamu 27:13) Iwọ nkọ? Ṣe iwọ naa ni igbagbọ pe iwọ naa yoo ri ire Oluwa ni ilẹ alaaye, ti ko si ni jẹ lẹyin igba ti o ba ku?

Ki a ma fọrọgun, emi ni igbagbọ pe emi yoo ri ire Oluwa ni ilẹ alaaye, pẹlupẹlu ninu orilẹ-ede Naijeria, bi o ti wu ki nkan ti igba n sọ lasiko yi ri. Mo ni igbagbọ bi eyi nitoripe mo mọ pe Ọlọrun, Baba wa, yoo ma fi igba gbogbo wa pẹlu mi lati jẹ ki ohun gbogbo ṣiṣẹ pọ ni rere fun mi. Adura mi wa ni pe ki iwọ naa gba okun lati le ma fi igbagbọ rin pẹlu Ọlọrun lati ni iriri ohun rere gbogbo ti O fẹ ki o ni laye yi, ni orukọ Jesu. Amin.

Kí o ní oṣù Ọ̀pẹ 2023 alárinrin.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ìbá má ṣe pé Olúwa wà níhà wá | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀pẹ 26, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 31 Read More »