January 2024

Lawọ́ sí Ọlọ́run | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Sẹrẹ 28, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 39

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o so oṣu Sẹrẹ ati Èrèlé ọdun yi pọ mọ ara wọn. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun ṣi oju rẹ si gbogbo igbesẹ ti o nilo lati gbe lati fi idi mulẹ sinu dídara rẹ ati sinu iṣerere ninu ọdun yi, ki O si tun fun ọ ni okun lati gbe wọn, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, ọkan lara awọn igbesẹ ti o nilo lati bẹrẹ si ni gbe lati fi idi mulẹ sinu didara Ọlọrun ati sinu iṣoriire lọdun yi ni lilawọ si Ọlọrun. Bawo ni a ṣe le fi han pe a lawọ si Ọlọrun? O kere ju, gbogbo wa ni a mọ pe Ọlọrun ko ni naa owo wa, jẹ ounjẹ wa tabi gbe ninu ile yowu ti a ba kọ fun un. Bawo wa ni a ṣe fẹ fi ilawọ han si?

Ni kukuru, a le fi ilawọ han si Ọlọrun, lakọkọ, nipa fifi nkan silẹ lati gbe iṣẹ rẹ laarin awọn eniyan lárugẹ. Ekeji, a le fi ilawọ han si nipa fifi fun awọn ti O ran lati ma bọ wa pẹlu ọrọ rẹ ati lati dari wa ni ipa ọna ododo. Ẹkẹta, a le fi han pe a lawọ si i nipa fifi fun awọn alaini ti o wa ni ayika wa. (Wo: Ditarónómì 15:7-11; 1Kiróníkà 29:1-9; Ìwé Òwe 19:17; Mátíù 25:40)

Ki wa ni idi ti o ṣe ṣe pataki ki a lawọ si Ọlọrun ni awọn ọna ti a mẹnuba yi? Akọkọ, o ṣe pataki nitoripe ki a ma la ọwọ si le ṣi ilẹkun silẹ fun aṣedanu ninu aye wa. Fun apẹrẹ, ninu iwe Wolii Hagai, a ri wipe idi kan pataki ti awọn eniyan Ọlọrun ti o pada wa lati ikọlọ Babiloni ṣe n ni iriri aṣedanu ni pe wọn pa kikọ tẹmpili Ọlọrun ti. Awọn eniyan wọnyi kan ṣa ri wipe bi o tilẹ jẹ wipe awọn n ṣiṣẹ karakara, iṣẹ karakara naa ko gbe iṣoriire larugẹ ninu aye wọn – o kan n ja si asan ni. Ti Ọlọrun ko ba wa lọ ran Hagai lati jẹ ki wọn mọ ibi ti nkan ti yiwọ ni, nṣe ni ọpọ wọn ko ba ṣegbe sinu iṣẹ. (Wo: Hágáì 1)

Nibakanna, ọpọ awọn onigbagbọ ni o jẹ wipe wọn n ṣiṣẹ bi erin loni ṣugbọn ti wọn n jẹ ijẹ ẹliri nitoripe wọn ko lawọ si Ọlọrun., Awọn naa, bi awọn eniyan igba aye Hagai, ma n fi gbogbo igba ni awawi kan tabi omiran lati ma fi nkan silẹ fun iṣẹ Ọlọrun, fun awọn iranṣẹ rẹ tabi fun awọn alaini ti o wa ni ayika wọn. Ti ko ba wa ṣe pe irufẹ awọn wọnyi ronupiwada, ki wọn si ma ṣe nkan ti o tọ, o ṣeeṣe ki wọn ku sinu iṣẹ nikẹyin-kẹyin. Ki eyi ma ṣe jẹ ipin rẹ laye, ni orukọ Jesu. Amin.

Siwajusi, o tun ṣe pataki ki a lawọ si Ọlọrun, ti a ba fẹ jẹ igbadun ere iṣẹ ọwọ wa. Jesu Oluwa wa sọ owe kan nipa ọkunrin ọlọrọ kan ti ilẹ rẹ ṣe daradara ni ọdun kan. Gẹgẹ bi O ti jẹ ki o ye wa, gbogbo ero ọkunrin yi ko wa kọja bi yoo ti ṣe kọ awọn àká (ilé-ìkó-oúnjẹ-pamọ́sí) ti o tobi ju awọn eyi ti o ni tẹlẹ lọ ati bi yoo ti ṣe farabalẹ bẹrẹ si ni gbadun ọrọ̀ rẹ fun ọpọlọpọ ọdun ti o n bọ. Ko tilẹ dupẹ lọwọ Ọlọrun tabi sọ ohunkohun nipa fifi nkan silẹ fun iṣẹ rẹ. Lafikun, ko sọ nkankan nipa riran awọn alufa ti o wa nilẹ naa lọwọ tabi nipa riran awọn alaini ti o wa ni ayika rẹ lọwọ. Ti ara rẹ nikan ni o n ro. Alánìkànjọ́pọ́n ati ahun eniyan gba a ni! (Wo: Luùkù 12:16-21)

Ki a ma fa ọrọ gun, nigba ti o ṣetan gbigboriyin fun ara rẹ ati sisọrọ nipa igbadun ọjọ́-ọ̀la rẹ, Ọlọrun fesi, O si sọ fun pe ni alẹ ọjọ ti a n wi yi gan ni a o bere ẹmi rẹ lọwọ rẹ. Eyi tunmọ si pe a ko ni fun ni aaye lati jẹ igbadun ere iṣẹ ọwọ rẹ. Awọn miran ni yoo jẹgbadun rẹ. Oluwa wa pari owe naa nipa sisọ pe bayi gẹlẹ ni yoo ti ṣe ri fun olukuluku eniyan ti o n to iṣura jọ fun ara rẹ ṣugbọn ti ko lawọ si Ọlọrun. Nitornia, ki a hawọ si Ọlọrun le ge ọjọ aye eniyan kuru. Mo si fẹ ki o fi eyi si ọkan.

Idi kẹta ti a fi nilo lati lawọ si Ọlọrun ni pe iṣoriire wa laye nigbamiran le sorọ mọ ọn. Fun apẹrẹ, fun opo Sarefati ati ọmọkunrin rẹ lati ma ku danu ati lati ṣerere ni asiko iyan aye Ọba Ahabu, o nilo lati lawọ si eniyan Ọlọrun ni, Elija. O wa ṣeeṣe pe obinrin yi ti lawọ sẹyin ni asiko ti o ni ọpọ. Amọ ko ki i ṣe ilawọ rẹ ni asiko ti o ni ọpọ ni o ṣi ilẹkun iṣẹ iyanu ipese fun ni asiko iyan yi. Dipo eyi, ilawọ rẹ ni asiko iyan naa, nigba ti o jẹ wipe nkan diẹ kerekere ni o ni lọwọ, ni o ṣi ilẹkun naa fun un. Ti ko ba wa fi tọkantọkan pin nkan ti o ni pẹlu eniyan Ọlọrun naa ni asiko yẹn nkọ? Ṣe yoo le la iyan naa kọja? Rara! (Wo: 1Awọn Ọba 17)

Nitorina, ọrọ Ọlọrun sọ wipe, “Eniyan kan n fun ni lọfẹ ẹ, sibẹ o n ni si i; omiran n hawọ ju bi o ti yẹ ṣugbọn o di alaini. Ẹni ti n ṣoore yoo maa gberu si i; ẹni ti o tu ẹlomiran lara yoo ni itura.” (Ìwé Òwe 11:24-25) Njẹ o ri bayẹn? Awọn ọ̀lawọ́ eniyan yoo ṣe rere. Ṣugbọn awọn ahun eniyan yoo pari aye wọn sinu ìṣẹ́. Nitori eyi, pinnu ninu ọkan rẹ lati lawọ si Ọlọrn lọdun yi ati la ma ya ahun si i. Ọlọrun yoo si fẹ aala iṣerere rẹ gbooro lọna ti o ga lotitọ. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ tí ó ga.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Lawọ́ sí Ọlọ́run | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Sẹrẹ 28, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 39 Read More »

Ǹjẹ́ o wà ní àrọ́wọ́tó rẹ̀? | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ṣẹrẹ 21, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 38

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu ọdun yi, ọdun 2024. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ya aye rẹ ya ohunkohun ti ko jẹ ki o wa ni arọwọto rẹ fun lilo lati bukun fun awọn miran, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, gbogbo igba ni Ọlọrun ma n wa awọn irinṣẹ ti O le lo lati fi idi ete rere rẹ mulẹ ninu aye awọn eniyan. O le jẹ ete rere rẹ lati wo wọn san, lati gba wọn la tabi lati jẹ ki wọn ṣoriire ni O fẹ mu ṣe. O ṣa ma n fi igba gbogbo nilo ọkunrin tabi obinrin kan tabi ọdọmọdekurin tabi odemọdebinrin kan ti o wa ni arọwọto rẹ lati lo nigbakigba ti O ba fẹ.

Fun apẹrẹ, O sọ eyi fun Isikiẹli nipa awọn eniyan Isiraẹli: “Emi si wa ẹnikan laarin wọn, ti iba tun odi naa mọ, ti iba duro ni ibi ti o ya naa niwaju mi fun ilẹ naa, ki emi ma baa parun: ṣugbọn emi ko ri ẹnikan.” (Ísíkíẹ̀lì 22:30) Iwọ naa wo bayẹn. Bi o tilẹ jẹ pe o tọ ki Ọlọrun ṣe idajọ awọn eniyan wọnyi nitori ọpọlọpọ ẹṣẹ wọn, ko si papa kanju lati ṣe idajọ wọn. Dipo bẹẹ, nṣe ni O n fi suuru wa gbogbo ilẹ naa boya Oun yoo tilẹ ri ẹnikan ti o n gbadura si Oun fun wọn, ki O ba le ṣaanu fun wọn. O wa ṣeni laanu pe ko ri ẹnikankan. Nitorina, ko si nkan miran ti O le ṣe ju ki O ṣe idajọ wọn lọ.

Nibakanna, ọpọ ni a ti fi silẹ lati jiya tabi lati ku nitoripe Ọlọrun ko ri ẹnikẹni lati lo lati mojuto wọn. Iwọ naa wo bi awa kan ṣe n gbadura ni gbogbo igba pe ki Ọlọrun da si ọrọ iṣedari orilẹ-ede yi. Ṣe o ro pe Ọlọrun ko ki i tẹti si wa ni? Tabi ṣe o ro wipe ko tilẹ wu u lati dahun adura wa ni? O kuku n tẹti siwa, O si tun n fi idahun si adura wa. Iṣoro ti o wa nibẹ ni pe O le ma ti ri ọkan kankan ni arọwoto rẹ fun lilo lati mu irufẹ itura ati ibalẹ ọkan ti a fẹ tọ wa wa. Nitorina, a tun nilo lati ma gbadura pe ki awọn ọkan ti O le lo lati gba orilẹ-ede wa la wa ni arọwọto rẹ.

Ṣugbọn awa gan an tilẹ wa ni arọwọto rẹ lati lo lati gba irufẹ awọn adura wọnyi? Ṣe a wa ni arọwọto rẹ fun lilo lati ṣe ohunkohun rara? Eleyi kọja ki a ma wa si awọn ipade ijọ wa. A le ma wa si awọn ipade ijọ wa, ki a si ma wa ni arọwọto Ọlọrun fun lilo lati bukun fun ẹnikẹni. Bi o ti ṣeeṣe ki o mọ, o ṣeeṣe ki agọ ara wa wa ninu ipade ijọ kan ṣugbọn ki a wa ni ibomiran ninu ọkan wa. Nitorina, nigba ti wọn ba ṣe awọn nkan ti o le bukun fun awọn miran, bi gbigbadura fun wọn, ninu ipade naa, ọkan wa ko kopa ninu rẹ. Bawo gan wa ni Ọlọrun ṣe fẹ ri wa lo lati bukun fun ẹnikẹni?

Ninu iwe isọtẹlẹ rẹ, Aisaya sọ ọrọ asiko kan ti o ba ara rẹ niwaju Ọlọrun ninu iran kan fun wa. Gẹgẹ bi o ti fi han wa, bi o tilẹ wa jẹ wipe o wa niwaju rẹ, Ọlọrun si tun n bere pe, “Tani n o ran? Tani yoo si lọ fun wa?” Kini idi ti Ọlọrun ko kan ṣe sọ pe, “Aisaya, mo fẹ ran ọ si awọn eniyan mi ki o ba le kọ wọn ni ọna mi?” Idi ni pe Ọlọrun ko ṣetan lati tan ara rẹ pe Aisaya wa ni arọwọto Oun fun lilo nitoripe o kan duro siwaju rẹ. Nitorina, Aisaya nilo lati fihan pe oun wa ni arọwọto rẹ fun lilo ki O to le ran lọ si ibikibi. (Wo: Àìsáyà 6:1-10)

Lọna kanna, pe a n wa si ipade ijọ ko to fun Ọlọrun lati lero wipe a wa ni arọwọtọ rẹ̀ fun lilo, iyẹn ti awa gan an ko ba fihan pe a wa ni arọwọto rẹ ati wipe O le lo wa. Wo ọpọ ijọ wa loni. Njẹ o mọ wipe awọn adari awọn ijọ yi ko kan le gba wipe a wa ni arọwọto wọn lati fun ni iṣẹkiṣẹ, biko ba ṣe pe a fihan pe a wa ni arọwọto wọn?

Fun apẹrẹ, ti o ba ma n fi igba gbogbo parẹ ni kete ti ipade ijọ kan ba ti pari, njẹ a le sọ wipe oun fi ara rẹ han bi ẹni ti o wa ni arọwọto lati ṣiṣe fun Ọlọrun ninu ijọ rẹ bi? Rara! Tabi ti iṣẹ kan ba wa ti ijọ fẹ ṣe, ti o ko si fi ara rẹ han lati kopa ninu rẹ, lalai ṣe pe o gba aye, ṣe awọn adari rẹ yoo ri ọ gẹgẹ bi ẹni ti o wa ni arọwọto lati darapọ mọ wọn ni ṣi ṣe iṣẹ fun Ọlọrun bi? Rara! Wo o, ẹni ti adari ijọ rẹ ba n ri ṣaaṣa ni sakani rẹ tabi ẹni ti o n fi gbogbo igba kan si i ni yoo ri bi ẹni ti o wa ni arọwọto oun lati jọ ṣiṣẹ Oluwa. Ko le ri ẹni ti o n fi gbogbo igba tabi ọpọ igba farapamọ fun un bi ẹni ti o fẹ nkan ṣe.

Nitorina, ti a ko ba wa ni arọwọto lati ṣiṣẹ pẹlu awọn adari tabi awọn ọmọ ijọ wa ninu awọn ipade wa, ki lo fẹ fi idi rẹ mulẹ pe Ọlọrun gan yoo ri wa bi ẹni ti o wa ni arọwọto rẹ fun lilo ni ibi iṣẹ wa, ile-iwe wa tabi adugbo wa? Ko si. Lotitọ, pe eniyan wa ni arọwọto Ọlọrun ko tunmọ si pe ẹni naa koju-oṣuwọn fun un lati lo. Amọ bi o tilẹ jẹ wipe awa ni a koju-oṣuwọn julọ fun iṣẹ ti O fẹ ṣe, niwọn igba ti a ko ba ti si ni arọwọto rẹ, ko si ni ki a ma jẹ alaiwulo fun un. Ibi ti eyi ba si ti ri bẹ ẹ, O ṣeeṣe ki Ọlọrun gba aṣálẹ̀ kan lọ lati lọ wa Mose kan lati lo tabi gba inu tubu lọ lati lọ mu Josẹfun miran jade wa tabi lọ si Babiloni lati lọ wa Nehemaya miran lati lo.

Adura mi ni pe ọrọ ko ni su Ọlọrun debi wipe yoo wa ẹni ti yoo fi rọpo wa lọdun yi, ni orukọ Jesu. Amin. Ọna kan ti a si fi le ma jẹ ki eyi waye ni pe ki a bẹrẹ lati ma fi ara wa si arọwọto rẹ fun lilo.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ tí ó ga.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ǹjẹ́ o wà ní àrọ́wọ́tó rẹ̀? | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ṣẹrẹ 21, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 38 Read More »

Sọ ọ́ dí mímúṣẹ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Àìkú 14, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 37

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ ni ailodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ kẹta ninu ọdun ọdun yi, ọdun 2024. Adura mi ni pe ki Ọlọrun fun ọ ni iyara lati ri erongba rere gbogbo ti O gbin sinu ọkan rẹ gbeṣe ninu ọdun naa, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi o ti ṣe han si gbogbo wa, ọdun yi ti n kuro diẹdiẹ ni ọdun tuntun lati di ògbólógbòó ọdun. Nitorina, ti a ba ri ohun rere kankan ti Ọlọrun fi si wa lọkan lati ṣe ninu ọdun naa, isinsinyi ni asiko lati bẹrẹ si ni gbe igbesẹ lati ṣe e. Jesu fi igbakanri sọ eyi fun awọn ọmọ ẹyin rẹ: “Awa ni lati ṣe iṣẹ ẹni ti o ran mi, niwọn igba ti o ba ti jẹ ọsan: oru n bọ wa nigba ti ẹnikan ki yoo le ṣe iṣẹ.” (Jòhánù 9:4) Njẹ o ri bayẹn? A ko ni gbogbo asiko ti o wa ni aye yi lati gbe erongba tabi ala rere yowu ti a ba ni fun ọdun yi ṣe. Nitorina, ti ko ba ṣe wipe a bẹrẹ ni kiakia lati ma ṣiṣẹ lati sọ ero tabi ala naa di otitọ, ilẹ yoo ṣu ba wa ki a to mọ ohun ti o n ṣẹlẹ, a o si ri wipe awọn nkan rere ti a fẹ gbeṣe ko jẹ ṣiṣẹ titi ọdun yi fi lọ.

Ọlọrun nikan ni o wa mọ iyẹ ilẹ ti o ti ṣu ba wa sẹyin, ti o si ti fi wa silẹ pẹlu awọn ero ati ala rere ti ko wa si imuṣẹ. Alẹ ọdun eyi naa yoo tun wa lẹ mọ wa lọwọ ati fi wa silẹ pẹlu awọn ero rere ti ko jẹ mimuṣẹ, ti a ko ba tete bẹrẹ si ni ṣiṣẹ lati jẹ ki wọn di mimuṣẹ. Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, Jakọbu, lẹyin igba ti o ti sin Labani fun ọdun melokan, ji lowurọ ọjọ kan lati ri wipe oun ko i ti ma ṣe ohunkohun fun ara rẹ ati ẹbi rẹ ti o n gbooro si. Gbogbo nkan ti o n ṣe ko ju ki o ṣiṣẹ fun ibatan oun ana rẹ lọ, ki o jẹ ati ki o mu ohun yowu ti o ba gbe le e lọwọ, ki o si tun bi ọmọ jọ.

Ṣugbọn ti ọkunrin yi ba wa binu si lọjọ kan nkọ, ti o si tun pinnu lati le e danu? Bawo ni yoo ṣe tẹsiwaju lati ma mojuto ebi rẹ? Tabi ti ọkunrin yi ba dede fosanlẹ, ti o si ku nkọ? Ṣe awọn ọmọ rẹ yoo pin ogun rẹ pẹlu rẹ? Ti wọn ba tilẹ pin ogun wọn pẹlu rẹ, ṣe nkan ti wọn yoo fun yoo to o lati bẹrẹ aye rẹ lakọtun ati lati tọju ẹbi nla ti o ni? Mo gbagbọ pe awọn ero wọnyi ni o n lọ ni ọkan Jakọbu ni asiko yi. Eyi si wa jẹ ki o pinnu pe ti oun ba ṣiṣẹ fun Labani pẹlu gbogbo awọn ọdun wọnni, ti oun ko si tun le mojuto ẹbi oun lalai jẹ wipe ọkunrin yi ba nawọ si oun, a jẹ wipe oun nilo lati kuro lọdọ rẹ ati lati wa nkan miran ṣe pẹlu aye oun. (Wo: Jẹ́nẹ́ṣíṣì 30:25-30)

Amọ ṣa o, Jakọbu ko gbero nikan lati kuro lọdọ Labani lati le mura fun ọjọ ọla idile rẹ, o tun gbe igbesẹ lati jẹ ki ero yi wa si imuṣẹ. Lọna wo? O fi igboya tọ Labani lọ lati sọ fun nkan ti oun ti pinnu lati ṣe. Lotitọ, Labani jẹ arakunrin iya rẹ. O si tun jẹ ana rẹ pẹlu, iyẹn baba awọn iyawo daradara rẹ mejeeji. Ṣugbọn ọrọ ọjọ ọla rẹ ati ti awọn aya ati ọmọ rẹ ni a n sọ nibiyi. Nitorina, ko fi aye gba itiju lati di i lọwọ lati ṣe nkan ti o tọ fun wọn. Lotitọ, a ko mọ bi o ti ṣe gba a ni asiko to lati ronu lori ọrọ yi ki o to gbe igbesẹ le lori. Ṣugbọn a mọ lati inu iwe mimọ pe lẹyin igba ti a bi ọmọ rẹ kọkanla, iyẹn Josẹfu, ni o sọ fun ara rẹ pe o to gẹẹ — oun nilo lati mu ero oun yi wa si imuṣẹ.

Bawo wa ni Labani ṣe tẹwọgba nkan ti Jakọbu sọ fun? Ṣe o binu si ni, ti o si sọ fun pe ko lọ ku danu? Rara o! Dipo ki o ṣe bẹyẹn, nṣe ni o bẹ ẹ pe ki o duro ti oun, ki o si sọ owo ọ̀yà rẹ. Kini idi? Idi ni pe oun funrarẹ mọ wipe oun ti n yan an jẹ lati ibẹrẹ wa ati wipe oun ko fun ni oun ti o tọ si fun iṣẹ aṣekara ti o n ṣe fun oun. Eyi, laifọrọgun, si ni ibẹrẹ iṣoriire Jakọbu, bi a ti ṣe fi han wa siwaju si ninu akọsilẹ naa. Nigba ti yoo si fi wa kuro lọdọ Labani, o ti di ọlọrọ eniyan. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 30-31)

Ti Jakọbu ko ba wa lọ ri idi fun un lati mura silẹ fun ọjọ ọla ẹbi rẹ ni asiko yi nkọ? Ṣe a ko ni le jade pẹlu ọwọ ofifo kuro ni ile Labani ni ọjọ kan? O di dandan ki a le jade kuro ni ile rẹ pẹlu ọwọ ofifo lọjọ kan. Ka tun wa sọ wipe ko gbe igbesẹ lori ero rẹ lati ṣe ohun ti o tọ fun ẹbi rẹ nkọ? Ṣe a ko si ni papa tabuku rẹ kuro ni ile Labani ni ọjọ kan? Ko fẹrẹ si ni ki o ma kan abuku jade kuro ni ile ọkunrin naa lati ọwọ awọn ọmọkunrin rẹ.

Nitorina, ni akọkọ, o ṣe pataki ki a ni ero ibi ti o yẹ ki a wa tabi nkan ti o yẹ ki o ma ṣẹlẹ laye wa ninu ọdun tuntun yi. Ṣugbọn eyi ko to. A tun gbọdọ bẹrẹ lẹsẹkẹsẹ lati ma fi igboya gbe awọn igbesẹ ti o tọ lati mu ki erongba wa jẹ mimuṣẹ, bi o tilẹ jẹ wipe eyi le bi awọn kan ninu. Aijẹbẹ, o ṣeeṣe ki o jẹ wipe ainitẹsiwaju tabi abuku ni a o fi ṣe ere jẹ ninu ọdun naa. Adura mi wa ni pe ki Ọlọrun ṣi oju rẹ lati ri ibi gbogbo ninu aye rẹ ti o ti yẹ fun igbega ati ti o ti yẹ ki o gbe igbesẹ fun ọjọ ọla ti o logo, ki O si tun ṣe ọ yẹ pẹlu ohun gbogbo ti o nilo lati gbe igbesẹ ti o tọ lati jẹ ki awọn nkan wọnyi di mimuṣẹ ninu ọdun yi, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Sọ ọ́ dí mímúṣẹ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Àìkú 14, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 37 Read More »

Ìhà yówù tí wọ́n le kọ sí ọ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Àìkú 07, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 36

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ titi lailai lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọdun tuntun yi, iyẹn ọdun 2024. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun mu wa si imuṣẹ ohun rere gbogbo ti O ni lọkan fun ọ ninu ọdun yi, ni orukọ Jesu. Amin.

Pataki julọ, o yẹ ki a fi ọpẹ fun Ọlọrun fun anfaani lati ri ọdun tuntun yi. Awọn kan wa ti o wu wọn lati ri ọdun naa ṣugbọn ti wọn ko si ni ibi mọ ni oni yi. Eyi ko si waye nitoripe awọn ni o buruju ni aarin awọn eniyan. O le jẹ wipe nitoripe asiko wọn ti to ni tabi nitoripe Satani ṣe aṣeyọri lati jẹ ki wọn ku siwaju asiko wọn tabi ki o jẹ wipe wọn ṣi ilẹkun aye wọn silẹ fun idajọ Ọlọrun nitoripe wọn fi oore-ọfẹ rẹ lori aye wọn ṣofo. Ohun yowu ki o jẹ, nkan ti o han kedere nipe a wa laye lati ri ọdun tuntun yi nitoripe Ọlọrun yan lati fi oju aanu rẹ wo wa ati lati fun wa ni asiko si lati gbe igbe aye ti yoo mu iyin wa fun un. Eyi si to gẹgẹ bi idi fun wa lati fi imoore wa han si i.

Wayi o, ọrọ iyanju mi si ọ, bi a ti ṣe n tẹsiwaju ninu irinajo wa sinu ọdun tuntun yi, ni pe ki o fi ara rẹ jin lati ṣe iṣẹ rere yowu ti Ọlọrun ba yan fun ọ lati ṣe, laifi ti iha yowu ti awọn ti o wa ni ayika rẹ le kọ si ọ ati si ohun ti o n ṣe ṣe. Kini idi? Idi ni pe nipa ṣiṣe ohun rere gbogbo ti O fẹ ki O ṣe gẹgẹ bi O ti ṣe fẹ ki O ṣe ni ogo re ṣe le farahan lẹkunrẹrẹ nipasẹ nkan ti o ṣe. Igba naa si tun ni iwọ naa yoo le ri ere ohun ti o ṣe gba lẹkunrẹrẹ.

Fun apẹẹrẹ, lẹyin igba ti Noa ti pari iṣẹ ti Ọlọrun gbe fun lati kan ọkọ ni ojo ti o pa aye igba rẹ run to rọ. Lẹyin igba yi naa si ni a to ya oun ati idile rẹ ya iwa ika ti o ti sọ aye igba naa di ibi ti o lewu lati gbe. Ṣugbọn, Noa nilo lati kan ọkọ naa ni ibamu pẹlu aṣẹ ti Ọlọrun ti fun un. Aijẹbẹ, bi o tilẹ jẹ wipe oun ati ẹbi rẹ wọ inu rẹ, wọn ko ba ma ti di ẹni igbala rara. Nitorina, ṣiṣe ohun gbogbo ti Ọlọrun fẹ ki a ṣe ko to lati ni iriri ogo, igbega ati igbala rẹ. A tun nilo lati ṣe ohun gbogbo ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ. Aijẹbẹ, a le ma ri ere gba rara fun iṣẹ yowu ti a ba ṣe fun. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 6-7)

Lafikun, bi a ti ṣe ri ninu bibeli, lẹyin igba ti Mose pari iṣẹ kikan agọ Ọlọrun, gẹgẹ bi Ọlọrun ti ṣe sọ fun pe ki o kan an, ni ogo Ọlọrun to sọkalẹ si ori rẹ. Nitorina, o ṣeeṣe ki o jẹ wipe idi ti o ko ṣe ti ni iriri ogo Ọlọrun ni awọn abala aye rẹ kan ni wipe o ko i ti ṣe ohun gbogbo ti Ọlọrun fẹ ki o ṣe ki ogo naa ba le farahan tabi pe o ko ma ṣe awọn nkan ti O fẹ ki oṣe ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ. Ti o ba wa gbajumọ ohun ti O fẹ ki o ṣe ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ, o di dandan ki o ri ifarahan ogo ti o yẹ ki o tẹle ṣiṣe bẹ ẹ lẹkunrẹrẹ. (Wo: Ẹ́kísódù 40)

Amọ ṣa o, a tun gbọdọ fi si ọkan pe irẹwẹsi ti ko ni jẹ ki a ṣe iṣẹ ti Ọlọrun fun wa, ki a si tun pari rẹ, le wa si ọkan wa lati ọdọ awọn ti o wa ni ayika wa. Fun apẹrẹ, aigbagbọ tabi inunibini wọn le fa irẹwẹsi si wa ni ọkan. Ranti wipe nigba ti Jesu lọ si ilu abinibi rẹ ko le ṣe iṣẹ iyanu pupọ ni aarin awọn eniyan rẹ nitori aigbagbọ ati inunibini wọn. Bibeli tilẹ sọ wipe ẹnu ya a gidigidi nitori aigbagbọ wọn. Ṣugbọn ṣe O wa jẹ ki eyi fa irẹwẹsi si lọkan, ki o si ma jẹ ki O tẹsiwaju lati ma ṣe iṣẹ ti Ọlọrun fun bi? Rara! Dipo bẹẹ, nṣe ni O tẹsiwaju lati ma lọ kaakiri lati kọni ati lati woni ṣan lati ibikan de ibomiran. Idi si ni pe O mọ wipe Oun gbọdọ pari iṣẹ ti Ọlọrun fun un, yala awọn eniyan tẹwọgba ati gbagbọ ninu rẹ tabi wọn ko ṣe bẹ ẹ. (Wo: Máàkù 6:1-6)

Yatọ si inunibini tabi aigbagbọ awọn eniyan, aimore wọn naa le tun fẹ fi irẹwẹsi si ọkan wa, ki o si tun di wa lọwọ lati ṣe ati lati pari awọn iṣẹ ti Ọlọrun gbe fun wa. Fun apẹrẹ, ni asiko kan, ọkan ṣoṣo lara awọn adẹtẹ mẹwa ti Jesu wosan ni o pada wa lati dupẹ lọwọ rẹ. O si ya a lẹnu pe awọn mẹsan yoku ko yọju rara lati kan sọ wipe, “Ẹ ma ṣe, ọgbẹni.” Amọ ṣe O jẹ ki eyi bu omi tutu si lọkan, ki o si di i lọwọ lati ma wo awọn miran ti o tọ ọ wa san bi? Rara! Kini idi? Idi ni pe O mọ wipe ẹni ti yoo pada dupẹ lọwọ Oun fun ohun gbogbo ti Oun n ṣe ni ẹni ti o ran oun niṣẹ, iyẹn Ọlọrun. (Wo: Lúùkù 17:11-19)

Nibakanna, bi awọn eniyan tilẹ kọ wa silẹ, ti wọn n bu wa tabi ti wọn kọ lati mọ riri ohun ti Ọlọrun n tipasẹ wa ṣe lọdun yi, a ko gbọdọ ba ọkan jẹ, ki a si pa iṣẹ rẹ tabi igbe aye ododo ti. Dipo eyi, nṣe ni a gbọdọ pinnu lọkan wa lati ṣe amulo oore-ọfẹ rẹ lati ṣe ohun gbogbo ti O fẹ ki a ṣe ninu ọdun yi ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ fun wa, iha yowu ti awọn eniyan le kọ si wa. Nipa ṣiṣe bayi, Oun yoo le mu ifẹ rẹ ṣẹ lẹkunrẹrẹ nipasẹ wa ati wipe awa naa yoo le wa ni ipo ti yoo fi le pin wa lere. Adura mi ni pe ki o gba okun lati rin ni ibamu pẹlu awọn ọrọ wọnyi ni gbigbe igbe aye rẹ fun Ọlọrun ati ni sisin in ninu ọdun yi, ni orukọ Jesu. Amin.

A kun ọdun tuntun o.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ìhà yówù tí wọ́n le kọ sí ọ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Àìkú 07, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 36 Read More »