Kò ní fi ẹlòmíràn rópọ̀ rẹ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èrèlé 25, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 43
Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o pari oṣu Èrèlé 2024. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun jẹ ki iwọ ati ohun gbogbo ti o jẹ tirẹ wa ni ailewu ati ni pipe ni gbogbo ọsẹ naa, ki O si tun ma jẹ ki o ṣe ohunkohun ti yoo jẹ ki o padanu ipo ti O ti yan fun ọ si ọwọ ẹlomiran, ni orukọ Jesu. Amin.
Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, Ọba Sọọlu, iyẹn ọba akọkọ fun orilẹ-ede Isiraẹli, ko ki i ṣe ààyò awọn eniyan tabi ààyò eniyan Ọlọrun ti o n dari orilẹ-ede naa ni asiko naa, iyẹn Samuẹli. Dipo eyi, ààyò Ọlọrun ni o jẹ. Ọlọrun funrarẹ ni O mọ-ọn-mọ ṣe awari rẹ, ti O si tun yan an lati jẹ ọba lori awọn eniyan rẹ. Sibẹsibẹ, ni asiko kan, Ọlọrun kọ ọ ni ọba, O si wa elomiran lati rọpo rẹ. (Wo: 1Sámúẹ́lì 9-15)
Ki ni eyi n sọ fn wa? Oun naa ni pe wipe Ọlọrun yan eniyan fun ipo tabi iṣẹ kan ko tunmọ si pe ko le kọ ẹni naa silẹ, ki O si wa ẹlomiran lati fi rọpo rẹ. O le ṣe bẹẹ. Amọ ṣa o, eyi ko wa jasi pe Ọlọrun yoo kọ ẹni naa silẹ gẹgẹ bi ọkan lara awọn eniyan rẹ. Ti a ko ba kọ Ọlọrun silẹ gẹgẹ bi Ọlọrun wa, Oun naa ko ni kọ wa silẹ gẹgẹ bi eniyan rẹ. Ṣugbọn O le kọ wa silẹ gẹgẹ bi ẹni ti ko yẹ tabi ti ko koju osuwọn fun ipo tabi iṣẹ ti O ti fi igba kan ri yan wa fun.
Fun apẹrẹ, bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun kọ Sọọlu ni ọba, ti O si tun fi ẹlomiran dipo rẹ, ko kọ ọ ṣilẹ gẹgẹ bi ọkan lara awọn eniyan rẹ. Ṣugbọn nigba ti Sọọlu kọ ọ gẹgẹ bi Ọlọrun, ti o si wa iranwọ lọ si ọdọ àjẹ́ kan, Ọlọrun naa kọ ọ gẹgẹ bi ọkan lara awọn eniyan rẹ. Nitorina, iṣoro yowu ti a le ma dojukọ, bi o tilẹ jẹ eyi ti a fi ọwọ ara wa fa sori ara wa ni, a ko gbọdọ lailai kọ Ọlọrun silẹ tabi yi pada kuro lọdọ rẹ. Aijẹbẹ, Oun naa ko ni ṣemeni-ṣemeji ju ki O kọ wa silẹ lọ. (Wo: 1Sámúẹ́lì 28; 2Tímótì 2:12)
Ki wa lo fa ti a fi kọ Sọọlu, ti a si tun fi ẹlomiran rọpo rẹ? Wo nkan ti awọn akọsilẹ iwe Mimọ yi sọ nipa rẹ:
“Samuẹli si wi fun un pe, “Iwọ hu iwa aṣiwere, iwọ ko si pa ofin ti Oluwa Ọlọrn rẹ fi fun ọ mọ, bi o ko ba ṣe bẹẹ, oun iba fi idi ijọba rẹ kalẹ lori Isirẹli laelae. Ṣugbọn nisinsin yii ijọba rẹ ki yoo duro pẹ, Oluwa ti wa ọkunrin ti o wu u ni ọkan rẹ fun ara rẹ, o si ti yan an lati ṣe olori fun awọn eniyan rẹ, nitori pe iwọ ko pa ofin Oluwa mọ.” (1Sámúẹ́lì 13:13-14)
“Ṣugbọn Samuẹli wi fun un pe, “Emi ko ni ba ọ pada. Iwọ ti kọ ọrọ Oluwa silẹ, Oluwa si ti kọ ọ ni ọba lori Isirẹli!”” (1Sámúẹ́lì 15:26)
Ṣe o ri wipe iṣoro Sọọlu ni pe ko mu ọrọ Ọlọrun ni pataki? Ṣugbọn Ọlọrun lo sọ ọ di ọba; ko sọ ara rẹ di ọba. Yatọ si iyẹn, Ọlọrun, ti o yan lati di ọba, tun fẹ fi idi ijọba rẹ mulẹ fun gbogbo igba. Ṣugbọn nitoripe, ni asiko kan, o bẹrẹ si ni ro wipe oun gbọn ju Ọlọrun lọ ati wipe oun le lọ aṣẹ Ọlọrun lọrun bi o ṣe wu oun, ki oun si tun tabuku wolii rẹ, Ọlọrun yi ọkan rẹ pada lori ọrọ rẹ, O kọ ọ silẹ, O si tun yan ọdọmọdekurin kan rọpo rẹ.
Nitorina, ti o ba ni aṣa ki o ma gbe oye rẹ leke awọn aṣẹ Ọlọrun fun aye rẹ, o wa labẹ ewu ki Ọlọrun kọ ọ silẹ, ki O si tun fi ẹlọmiran rọpo rẹ fun awọn ipo giga tabi awọn iṣẹ rere kan ni aye yi, bi o tilẹ jẹ wipe iwọ ni ẹni naa ti a kọkọ yan fun wọn. Lotitọ, o le ni awọn idi ti o fi ma n fẹ ki ifẹ tirẹ leke ifẹ Ọlọrun tabi ti o ko fi ni ọ̀wọ̀ ti ko nitunmọ kankan fun awọn ti o yan le ọ lori. Ṣugbọn ni opin ohun gbogbo, iwọ naa yoo ri wipe awọn idi wọnyi ko kọja awawi asan ti Ọlọrun ko le lailai tẹwọgba.
Sọọlu naa ni awọn idi ti o fi tabuku ọrọ Ọlọrun ati wolii rẹ. Itara gbigbona rẹ lati di itẹ rẹ mu jẹ ọkan. Ibẹru awọn jagunjagun rẹ jẹ omiran. Ṣibẹsibẹ, Ọlọrun kọ ọ, O si tun fi ẹlomiran rọpo rẹ. Ko si wa si nkankan ti o ṣe lati gba itẹ rẹ fun awọn arọmọdọmọ rẹ ti o ṣiṣẹ. Ko si si nkankan ti awa naa le ṣe lati gba ipokipo tabi iṣẹkiṣẹ ti Ọlọrun ba ti gba kuro lọwọ wa fun ara wa. Nitorina, nṣe ni ki a ṣọ ara wa, ki a si ma fi aye gba aigbagbọ, agidi-inu, ibẹru, itara-gbigbona, ojukokoro, ifẹkufẹ, ẹtanu, igberaga, ilara tabi ohun miran lati fi aye silẹ fun un lati fi ẹlomiran ropo wa. Adura mi si ni pe ki a ma fi gbogbo igba kun wa pẹlu ọgbọn ati okun ti o peye lati rin pẹlu afiyesi eyi, ni orikọ Jesu. Amin.
Ki o ni ọsẹ alarinrin.
Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

