March 2024

Agbára rẹ̀ wá ní àrọ́wọ́tó wá | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 31, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 48

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ tuntun ati sinu ọjọ ti o gbẹyin oṣu yi. Mo si gbadura pe, bi a ti ṣe n wọ inu oṣu tuntun lọ lọsẹ yi, iyẹn oṣu Igbe 2024, ki Ọlọrun jẹ ki agbara rẹ ti o ji Jesu Oluwa wa dide kuro ninu oku ji iwọ naa dide lati ibi ti o wa lọ si ibi ti o yẹ ki o wa laye, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi gbogbo wa ti ṣe mọ, ọpọ Kirisitiẹni kaakiri agbaye loni ni o n yọ ayọ ajinde Jesu Kirisiti Oluwa wa. Eyi si tọna. Amọ ṣa o, ayọ ajinde rẹ gbọdọ kọja eyi ti a n ya ọjọ kan silẹ lati yọ; dipo bẹẹ, o yẹ ki o jẹ eyi ti a o ma fi ojoojumọ yọ ayọ rẹ. A o si ma yọ ayọ ajinde rẹ lojoojumọ ati ni gbogbo asiko ninu aye wa, ti a ba ni oye ti o peye nkan ti o tunmọ si fun wa.

Wayi o, ki wa ni ajinde rẹ tunmọ si fun wa? Ki a sọ otitọ, bibeli menuba melokan ninu awọn nkan ti o tunmọ si fun wa. Ọkan lara rẹ si ni pe o fi agbara kanna ti o ji dide kuro ninu oku si arọwọto awọn ti o gbagbọ ninu rẹ. Wo bi Pọọlu ti ṣe gbe eyi kalẹ ninu adura rẹ kan fun awọn ijọ:

“Ki oju ọkan yin lee mọlẹ; ki ẹyin ki o le ni oye ohun ti ireti ipe rẹ jẹ ati ohun ti i ṣe ọrọ̀ ogo ini rẹ ninu awọn eniyan mimọ rẹ, ati agbara rẹ ti o tobi julọ si awa ti o gbagbọ, gẹgẹ bi iṣẹ agbara rẹ, eyi ti o tiṣe pari ninu Kirisiti nigba ti o ji i dide kuro ninu oku, ti o si mu un jokoo ni ọwọ ọtun ninu awọn ọrun. O gbe e ga ju gbogbo ijọba oju ọrun, ati agbara, ati ipa, ati ilẹ ọba, ati gbogbo orukọ ti a n da, ki i ṣe ni aye yii nikan ṣugbọn ati ni eyi ti n bọ pẹlu.” (Efesu 1:18-21)

Ki ni afojusun adura Pọọlu nibiyi? Akọkọ, o ni i ṣe pẹlu pe ki Ọlọrun ṣi oju wa lati le mọ ireti ayeraye ti O ti pe wa si. Ekeji, o ni i ṣe pẹlu pe ki O fi oye bi ini rẹ ninu wa, iyẹn awọn nkan daradara ti O ti gbin sinu aye wa, ti ṣe lọrọ ati logo to. Ẹkẹta, o ni i ṣe pẹlu pe ki Ọlọrun jẹ ki a da agbara rẹ ti ko lakawe, ti o ga, ti o si wa fun awa ti o gbagbọ mọ.

Ki wa ni Pọọlu sọ nipa agbara Ọlọrun ti ko lakawe, ti o si tun ga, yii? O sọ wipe o wa fun awa ti o gbagbọ. Iyẹn jasi pe agbara Ọlọrun wa ni arawọto iwọ ati emi lati ṣe amulo. Ṣugbọn a ko ni ṣe amulo rẹ lọna ti o peye, ti a ko ba mọ bi o ti ṣe tobi ati bi o tun ti ṣe lagbara to.

Nitorina, Pọọlu fun wa ni apẹrẹ kan ti o ni i ṣe pẹlu iṣẹ ati titobi agbara naa. Eyi si ni ti ajinde Jesu Kirisiti Oluwa wa kuro ninu oku. Gẹgẹ bi O ti ṣe sọ, agbara yi ni Ọlọrun tu sinu Jesu nigba ti O fẹ ji dide kuro ni ipo oku. Nitorina, lalai ṣe wipe ẹnikẹni gbadura tabi aawẹ fun ati laiṣepe ẹnikẹni gbe ọwọ le lori, agbara yi tu u silẹ kuro lẹnu iku, bi o tilẹ jẹ wipe O ti ku fun ọjọ mẹta. Aleluya!

Pọọlu tun wa tẹsiwaju lati sọ fun wa pe agbara yi kanna ni o jẹ ki o ṣeeṣe fun Jesu lati goke re ọrun ati lati joko si ọwọ ọtun Ọlọrun, nibi ti o ga fiofio ju gbogbo awọn alaṣẹ ati alagbara ati ju gbogbo orukọ ati oye ti a le fun ni lọ, Nitorina, a n wo agbara niwaju eyi ti iku ko ti le duro. Bẹẹni, a n wo agbara ti a ko le di lọwọ lati gbe awọn ti Ọlọrun ba fẹ ẹ gbega lọ si ibi ti O fẹ ki wọn wa. A si ti wa fi agbara yi si arọwọto awa ti o gbagbọ. Yatọ si eyi, agbara naa tun wa n ṣiṣẹ ninu wa lọwọlọwọ yi. (Wo: Efesu 3:20)

Nitorina, lakọkọ, nṣe ni o yẹ ki a ma fi igba gbogbo fi ọpẹ fun Ọlọrun fun bi O ti ṣe fi agbara yi, agbara ajinde ati igbasoke Krisiti, si arọwọto wa. Ekeji, nṣe ni o yẹ ki a ma gbadura ni gbogbo igba, gẹgẹ bi Pọọlu, pe ki Ọlọrun jẹ ki a mọ riri agbara yi, ki a si tun ma ṣe amulo rẹ lati bori gbogbo idojukọ aye yi ati lati jẹ irufẹ eniyan ti Ọlọrun fẹ ki a jẹ. Nje ki a gba okun nipasẹ Ẹmi Ọlọrun lati fi ara wa jin fun ṣiṣe awọn nkan wọnyi, ki awọn anfaani ti o sọrọ mọ ajinde Jesu Kirisiti Oluwa wa ma ba fo wa ru. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ tí ó ga.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Agbára rẹ̀ wá ní àrọ́wọ́tó wá | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 31, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 48 Read More »

Àwa náà le ṣe ohun tí a kà sí kò-ṣeéṣeLáti | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 24, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 47

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lọpọlọpọ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o kẹyin oṣu Ẹrẹ́nà 2024. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun fun ọ ni okun lati ma fi igba gbogbo tẹ oju rẹ mọ ọn ati mọ ọrọ rẹ, ki o ba le rin ni iṣẹgun lori gbogbo idena aye, ki o si da ohun gbogbo ti O fẹ ki o da, ni orukọ Jesu. Amin.

Ninu iwe iyinrere Matiu, o kọ akọsilẹ iṣẹlẹ kan fun wa ninu eyi ti Jesu ti rin lori omi. Bi akọsilẹ naa si ṣe lọ, ni alẹ ọjọ kan ati lẹyin ipade kan, Jesu jẹ ki awọn ọmọ ẹyin rẹ wọ inu ọkọ oju omi lọ lati ṣaaju rẹ lọ si ibi kan ti a n pe ni Gẹnẹsareti, nigba ti Oun si lọ gbadura. Ko si wa si ọkankan ninu wọn ti o tilẹ bikita lati bere pe bawo ni yoo ṣe darapọ mọ wọn. Wọn kan kuro naa ni nitoripe O ti sọ pe ki wọn maa lọ. (Wo: Mátíù 14:14-22)

Amọ ṣa o, nigba ti O ṣetan nidi adura gbigba, ti O si ri wipe afẹfẹ n fẹ lodi si wọn, O jade tọ wọn lọ nipa ririn lori omi. Nigba ti wọn si ri eyi, ẹru ba gbogbo wọn, wọn si bẹrẹ si ni pariwo ninu ìpayà, pẹlu ero wipe iwin ni awọn n ri. Ṣugbọn O sọ fun wọn pe ki wọn ma bẹru ati wipe Oun ni ẹni naa. (Wo: Mátíù 14:24-27)

Wayi o, ni kete ti Peteru gbọ pe Jesu ni O n rin lori omi ni o sọ wipe, “Oluwa, ti O ba ṣe pe Iwọ ni, paṣẹ ki emi ki o tọ ọ wa ni ori omi.” Ṣe o ronu nipa eyi ki o to sọ bi? Rara o! Ṣugbọn, nibikan ninu ọkan rẹ, o ṣaa mọ wipe ti o ba je pe Jesu Oluwa wa ni O n rin lori omi nitootọ, O wa ni ipo lati sọ ọrọ aṣẹ ati agbara ti yoo jẹ ki oun naa le ṣe bẹẹ gẹgẹ. Nkan ti o si sẹlẹ gan an niyẹn? Nigba ti o bere nkan yi, Jesu dahun, O si wipe, “Wa!” (Wo: Mátíù 14:28-29)

Ṣe Peteru wa rin lori omi tabi ko rin lori rẹ? O rin lori rẹ! O rin lori omi ni gbangba loju awọn ọmọ ẹyin yoku ti wọn wa pẹlu rẹ ninu ọkọ oju omi naa. Amọ ṣa o, Matiu tẹsiwaju lati sọ fun wa pe nigba ti ọkunrin yi ri iji, ẹru ba a, o si bẹrẹ si ni ri sinu omi. O wa pariwo si Oluwa lati gba a la. Ṣe O wa gba a la tabi ko gba a la? O gba a la, awọn mejiji si jọ rin pada lori omi sinu ọkọ oju omi naa. Ṣugbọn O sọ fun pe idi ti o ṣe bẹrẹ si ni ri ni pe o ṣiyemeji ati wipe iyemeji rẹ ni o fi irẹwẹsi si inu igbagbọ rẹ ti o ga, ti o si sọ di igbagbọ kekere. (Wo: Mátíù 14:28-32)

Ki a ma fọrọgun, titi aye ni yoo wa ninu akọsilẹ pe Peteru ṣe ohun ti a ka si kò-ṣeéṣe nipa ririn lori omi pẹlu Jesu Oluwa wa. Bẹẹni, titi aye ni yoo wa ninu akọsilẹ pe o ṣe ohun ti awọn ọmọ ẹyin Oluwa yoku ko ṣe. Ki ni idi? Akọkọ, idi ni pe o wa lori ẹmi rẹ lati ṣe e. Ekeji, idi ni pe Oluwa sọ ọrọ jade pe o le ṣe e. Se o ri, nini erongba lati ṣe nkan tabi lati ni nkan ko to. Ti ko ba si ọrọ Ọlọrun lati gbe nkan naa lẹsẹ, inira tabi iparun ni yoo yọri si. Eyi tunmọ si pe igbagbọ ninu Ọlọrun gbọdọ da lori ọrọ rẹ dipo lori erongba tabi bi nkan ṣe ri lara wa tabi lori iriri awọn miran. A si wa ri awọn ti wọn ti fi aimọkan-mọkan ṣe ara wọn leṣe nibi ti wọn ti n gbiyanju lati lo igbagbọ ti a ko pilẹ sori ifihan ọrọ Ọlọrun ti o peye.

Idi kẹta ti Peteru fi rin lori omi pẹlu Jesu ni pe o ṣiṣẹ lori ọrọ Oluwa ti o sọ pe, “Wa!” Ti ko ba ṣiṣẹ lori ọrọ naa ni, ko ba ma ti rin lori omi bi o ti ṣe ṣe. Ṣugbọn wa kiyesi pe nigba ti Oluwa da Peteru lohun, ko sọ wipe, “Wa, Peteru!” Dipo bẹ ẹ, nṣe ni O sọ wipe, “Wa!” Eyi tunmọ si pe ọrọ aṣẹ ati agbara wa fun gbogbo wọn ti o wa ninu ọkọ oju omi naa. Ṣugbọn Peteru nikan ni o ṣiṣẹ le lori. Peteru nikan ni o sọkalẹ kuro ninu ọkọ oju omi naa, ti o si rin lori omi. Awọn yoku kan duro sinu ọkọ oju omi naa pẹlu iyanu ni, ti wọn si n wo ọrẹ ati alabaṣiṣẹpọ wọn bi o ti ṣe n rin lori omi lati lọ pade Jesu.

Ki ni idi ti eyi ṣe wa ri bẹ? O ri bẹ ẹ nitoripe Peteru nikan ni o ni ifẹ ati itara ti o ga to ninu ọkan rẹ ni asiko yi lati ṣe ohun ti Oluwa sọ wipe gbogbo wọn le ṣe e. Ẹkọ ti eyi si kọ wa ko le rara. Oun naa si pe awa naa le ya ara wa sọtọ kuro laarin awọn miran lati ṣe ohun ti a ka si kò-ṣeéṣe nipasẹ igbagbọ wa ninu Jesu Oluwa. Bẹẹni awa naa le rin lori awọn omi aisan, iṣẹ, ainilọsiwaju, ibẹru ati iku. Idi si ni pe ọrọ Ọlọrun ti sọ wipe a le ṣe bẹ ẹ. Nkan ti a wa nilo naa ko ju pe ki a ni itara ti o ga lati ṣe bẹ ẹ, ki a ma fi ojoojumọ gbe igbesẹ igbagbọ ti Ọlọrun n sọ fun wa pe ki a gbe, ki a si tẹjumọ Jesu. Ki ẹnikẹni si to mọ nkan ti o n ṣẹlẹ, a o ti ṣe nkan ti a ka si kò-ṣeéṣe, a o si tun ti silẹkun silẹ fun ọpọ lati yin Ọlọrun nipasẹ wa.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Àwa náà le ṣe ohun tí a kà sí kò-ṣeéṣeLáti | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 24, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 47 Read More »

Ìwọ náà le jẹ́ olùtùnú | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 17, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 46

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lailodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ẹrẹna 2024. Adura mi fun ọ ni pe ki Ọlọrun jẹ ki o ni iriri itunu rẹ ni gbogbo ọna, ki iwọ naa ba a le jẹ olutunu fun gbogbo awọn ti o wa ninu aye rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ninu lẹta rẹ si awọn ara Kọrinti, Pọọlu sọ awọn ọrọ wọnyi ti o ṣe pataki ki a kiyesi: “Olubukun ni Ọlọrun, ati Baba Jesu Kirisiti Oluwa wa, Baba ìyọ́nú, ati Ọlọrun itunu gbogbo; Ẹni ti n tu wa ninu ni gbogbo idaamu wa, ki awa le maa pẹlu tu awọn ti o wa ninu idaamu ninu, nipa itunu naa ti a n fi n tu awa funra wa ninu lati ọdọ Ọlọrun wa.” (2Kọ́ríntì 1:3-4) Ki ni idi ti Pọọlu ṣe yin Ọlọrun ninu ẹṣẹ bibeli yi: O yin in nitoripe O jẹ olutunu fun un.

Njẹ iwọ naa wa mọ Ọlọrun gẹgẹ bi olutunu bi? Pọọlu sọ fun wa pe olutunu ni. O tilẹ sọ siwaju pe Ọlọrun ju ẹni ti a le pe ni olutunu lọ — Oun gan ni Baba aanu ati Ọlọrun gbogbo itunu otitọ. Eyi jasi pe, ọdọ Ọlọrun ni ohun gbogbo ti a n pe ni aanu ati itunu otitọ ti n jade wa. Nitorina, ti o ba nilo aanu ati itunu ninu aye rẹ, fi tọkan-tọkan kọju si Ọlọrun. Yoo si fi aanu ti o ga han ọ, yoo si tun tu ọ ninu ni gbogbo ọna, lalai wo ailera ati ikuna rẹ

Bi Pọọlu ti ṣe fi han wa ninu ẹṣẹ bibeli yẹn, bi o tilẹ jẹ wipe oun ati awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ ba oniruuru iṣoro ati idojkọ pade laye, Ọlọrun tu wọn ninu ninu ọkọọkan ninu awọn nkan wọnyi. Ọna wo ni Ọlọrun gba ṣe e? Ko salaye eyi fun wa. Amọ daju ṣaka ni pe irufẹ itunu ti wọn gba lọdọ Ọlọrun ga debi wipe wọn kun fun iyin nitori rẹ. Lafikun, irufẹ itunu ti wọn ri gba lọdọ rẹ ga debi wipe awọn naa tun le tu awọn miran ti o wa ninu idamu ninu pẹlu rẹ.

Eyi si n fi han wa pe kiki awọn ti o ti ni iriri aanu ati itunu Ọlọrun nitootọ, ti wọn si mọ-ọn lore nikan ni o le tu awọn miran ninu lotitọ. Awọn ti ko mọ aanu ati itunu Ọlọrun ko le je olutunu otitọ fun awọn ti iya n jẹ tabi ti ara n ni ni ayika wọn. Wo awọn ọrẹ Jobu, fun apẹrẹ. Bi o tilẹ jẹ wipe ọlọrọ, ọlọgbọn ati olododo ni gbogbo wọn jẹ, wọn ko le tu u ninu ni asiko inira rẹ. Nṣe ni wọn kan tun da kun irora rẹ. Ki ni idi? Idi ni pe wọn ko mọ pe gbogbo itura ti awọn n jẹ igbadun ninu aye wọn ko wa nitori iṣẹ ododo ati iṣẹ afọkanṣe wọn ṣugbọn nitori aanu Ọlọrun.

Nibakana, ti awa naa ba ro wipe irufẹ itura yowu ti a n jẹ igbadun jẹ eyi ti o tọ si wa, a ko ni ri idi kankan lati ṣaanu fun awọn miran ati lati tu wọn ninu. Dipo bẹẹ, ọpọ igba ni a o ma woye lọkan wa pe wọn n jẹ iya nitoripe wọn ko ki i ṣe olododo tabi nitoripe wọn ko jafafa lẹnu iṣẹ to. Amọ, a ko ma jẹgbadun aye wa nitoripe a jẹ olododo ati ẹni ti o jafafa lẹnu iṣẹ, bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun fẹ ki a jẹ olododo ati ẹni ti o jafafa lẹnu iṣẹ. Dipo bẹẹ, a n jẹ igbadun aye wa nitoripe Ọlọrun yan lati ṣaanu fun wa ati lati tu wa lara. Ti a ba si wa kọ lati mọ eyi, ki a si ma fi iyin fun nitori rẹ, a le bẹrẹ si ni padanu irufẹ itura yowu ti a le ni titi a o fi mọ, ti a o si tun gba pe Oun ni orisun gbogbo itura.

Ni kukuru, koko nkan ti a n sọ nipe ti o ba fẹ itura ni ọnakọna ninu aye rẹ lọwọlọwọ yi, kọju si Ọlọrun, Baba aanu ati Ọlọrun itunu fun un. Yoo si fi aanu ati itura fun ọ. Siwaju si, bi o ba ti ṣe n fi ojoojumọ ni iriri itura ninu aye rẹ, ṣi oju rẹ silẹ lati ri awọn ti o wa ni ayika rẹ ti iwọ naa le tu ninu pẹlu itunu ti o rigba lọwọ rẹ. Eyi si wa kọja ki a fun eniyan lowo. Idi ni pe a ri awọn ti o jẹ pe ara ko le tu wọn rara, bi a tilẹ fun wọn ni gbogbo owo ti o wa ninu aye yi. Ṣugbọn gbolohun adura kan tabi ọrọ iyanju kan ti a ba sọ fun wọn nipasẹ idari Ẹmi Ọlọrun le tu wọn silẹ kuro lọwọ gbogbo ibẹru ati idaamu wọn, ki o si kun aye wọn pẹlu itura.

Nitorina, ma ṣe gbẹkẹle owo tabi ipo rẹ ni titu ẹnikẹni ninu. Dipo bẹẹ, gbẹkẹle Ọlọrun, ẹni ti o jẹ orisun gbogbo itunu, fun ohun gbogbo ti o nilo lati tu awọn ti o wa ninu aye rẹ ninu lotitọ. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ṣe o ni olutunu otitọ fun gbogbo awọn ti o wa ni ayika rẹ ti o wa ninu inira, ki wọn ba le fi ogo fun orukọ rẹ nitori rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ìwọ náà le jẹ́ olùtùnú | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 17, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 46 Read More »

Taló sọ pé kí wọ́n kúrò | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 10, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 45

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia di ọpọlọpọ fun ọ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Erele 2024. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun kun ọkan rẹ pẹlu imọ ti o peye lori awọn igbese ti o yẹ ki o gbe lati rin ni iṣẹgun lori awọn iṣoro iṣuna ati aabo ti orilẹ-ede yi n ba finra lọwọlọwọ yi, ni orukọ Jesu. Amin.

Ko ki i ṣe iroyin mọ ni pe orilẹ-ede wa n doju kọ awọn ipenija ti o ga lori eto isuna ati ọrọ aabo rẹ. Idasi Ọlọrun nikan si ni o le mu wa laa ja. Idi si ni yi ti awa ti a mọ ọn ko fi gbọdọ dẹkun lati ma gbadura si i titi ayọ wa yoo fi kun lori orilẹ-ede naa. Ranti pe Jesu Oluwa wa sọ fun wa pe ki a bere titi ayọ wa yoo fi kun. Nitorina, niwọn igba ti ayọ wa ko ba i ti kun lori orilẹ-ede wa, a gbọdọ tẹsiwaju lati ma gbadura si Ọlọrun fun un. (Wo: Jòhánù 16:24)

Amọ ṣa o, bi a ti ṣe n fi itara reti pe ki Ọlọrun dasi ọrọ wa, ki O si gba orilẹ-ede wa la, bẹẹ na ni awa, gẹgẹ bi ẹnikọọkan, tun ṣe nilo lati mọ awọn igbesẹ ti o tọ fun wa lati gbe lati gberu ni orilẹ-ede yi dipo eyi ti awọn iṣoro rẹ yoo fi pa wa run. Ẹnikan ṣoṣo ti O si le fi eyi han wa ni Ọlọrun. Nitorina, bi a ti ṣe n gbadura si fun orilẹ-ede wa, a tun gbọdọ ma gbadura si fun ara wa. A gbọdọ ma gbadura si pe ki O kun ọkan wa pẹlu imọ ti o peye nipa ohun ti o ye ki a ṣe lati la asiko ipenija orilẹ-ede yi kọja, ki a si yege. Ti a ba si fi tọkantọkan ṣe bẹẹ, O di dandan ki O dawa lohun, ki O si dari wa ni oju ọna ti o yẹ ki a tọ.

Tun ranti pe ọrọ Ọlọrun sọ fun wa pe ki a gbẹkele Ọlọrun pẹlu gbogbo ọkan wa, ki a kaa si ni gbogbo ọna wa, ki a si tun ma ṣe tẹ si oye tara wa. Nipa eyi, Oun yoo dari wa nipa ọna iṣẹgun. O wa ṣeni laanu pe ọpọ laarin awọn ti o tilẹ jẹ eniyan Ọlọrun ni ko gbe ọkan wọn le mọ lati dari wọn si ọna ti o yẹ ki wọn tọ ni asiko yi. Nṣe ni wọn n gbojule ọgbọn ati oye wọn. O si wa di dandan ki awọn ti o n ṣe eyi ba ẹtẹ pade, bopẹ-boya, ti a ko ba fi aanu han si wọn lati ọdọ Ọlọrun. (Wo: Ìwé Òwe 3:5-6)

Ranti itan Naomi ati awọn ẹbi rẹ. Gbogbo wọn ni o fi ilẹ Isiraẹli silẹ lọ si ilẹ Moabu nitoro pe iyan kan ti o le gan mu ni ilẹ naa. Ṣugbọn tani o sọ fun wọn pe ki wọn kuro? Ṣe Ọlọrun ni? A ko sọ fun wa rara. Ṣugbọn a sọ fun wa pe Naomi pada kabamọ lori nkan ti wọn ṣe. Idi si ni pe oun nikan ni o pada wa si ile laaye. Ati pe bi o tilẹ jẹ wipe o pada laaye, nṣe ni o pada pẹlu ọwọ ofifo. (Wo: Rúùtù 1)

Amọ wa wo ọrọ arabinrin Ṣunemu, ẹni ti Eliṣa fi igbakanri ji ọmọkunrin rẹ dide kuro ni ipo oku. Asiko kan naa wa ti oun naa kuro ni ilẹ Isiraẹli pẹlu awọn ara ile rẹ nitori iyan. Ṣugbọn ṣe o padanu ẹbi rẹ tabi nkan ini rẹ kankan nibi ti wọn ṣipo-pada lọ? Rara! Dipo eyi, bi a ti ṣe fi han wa ninu bibeli, nigba ti iyan naa kasẹ nlẹ tan, o pada wa silu pẹlu awọn eniyan rẹ, ninu okun ati ilera. Yatọ si eyi, ọba tun paṣẹ pe ki a da ohun gbogbo ti o fi silẹ pada fun, iyẹn pẹlu gbogbo owo ti a pa lori awọn nkan ini rẹ. (Wo: 2Àwọn Ọba 8:3-6)

Ki ni idi ti arabinrin fi ri ojurere gba bi eyi? Idi ni pe igbeṣẹ ti o gbe lati kuro ni ilẹ naa ni asiko iyan yi jẹ eyi ti Oluwa pa laṣẹ fun un. Wo nkan ti bibeli sọ nipa eyi: “Eliṣa si wi fun obinrin naa, ọmọ ẹni ti o ti sọ di aaye wi pe, “Dide, si lọ, iwọ ati ile rẹ, ki o si ṣe atipo nibikibi ti iwọ ba le ṣe atipo: nitori ti Oluwa pe iyan: yoo si mu pẹlu ni ilẹ yii ni ọdun meje. Obinrin naa si dide, o si ṣe gẹgẹ bi ọrọ eniyan Ọlọrun naa? Oun si lọ pẹlu ile rẹ, wọn si ṣe atipo ni ilẹ awọn ara Filisitini ni ọdun meje.” (2 Awọn Ọba 8:1-2)

Njẹ o ri bayẹn? Arabinrin yi ko sa kuro ni ilẹ naa pẹlu awọn ẹbi rẹ nitoripe o kan ro wipe nkan ti o tọ fun oun lati ṣe niyẹn. Dipo eyi, o fi ilẹ naa silẹ nitoripe adari rẹ ninu ẹmi, Wolii Eliṣa, sọ fun pe ifẹ Ọlọrun ni fun lati ṣe bẹẹ. Nitorina, nṣe ni o ṣe nkan ti o ṣe ni gbigbọran si aṣẹ Ọlọrun. Alabajọ ti ko ṣe kabamọ lori rẹ.

Awa naa ko ni kabamọ lori awọn igbesẹ wa, ti a ba jẹ ki Ọlọrun dari wa ni asiko rogbodiyan ti ilẹ wa lapapọ n ba finran lasiko yi, dipo ti a o kan fi ma fo lati ibikan si ibikan lati ṣe ohun yowu ti o ba ko si wa lọkan tabi ohun yowu ti awọn ti o wa ni ayika wa n ṣe. Yoo si dari wa, ti a ba le gbadura si lati ṣe bẹẹ. Lọna wo? O le jẹ nipasẹ iwe mimọ, nipasẹ iran tabi ala, nipasẹ awọn angẹli tabi nipasẹ awọn adari wa ninu ẹmi. Ṣugbọn dandan ni ki Ọlọrun dari wa lati ṣoriire, pẹlu bi gbogbo nkan ti ri yi, niwọn igba ti a ba ṣi ọkan wa paya fun lati dari wa.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Taló sọ pé kí wọ́n kúrò | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 10, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 45 Read More »

Ìfẹ̀hónúhàn kò tó | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 03, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 44

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu oṣu miran ninu ọdun yi, oṣu Ẹrẹna 2024. Adura mi ni pe ki Ọlọrun mu asiko itura wa fun wa ni ibi gbogbo ni orilẹ-ede yi loṣu naa, ki O si tun pa iwọ ati ẹbi rẹ mọ lati jẹ igbadun asiko itura ti O ba fun wa ni ẹkunrẹrẹ. Amin.

Gẹgẹ bi gbogbo wa ti ṣe le ri, a ti sọ orilẹ-ede wa sinu asiko iyan ti o buru jọjọ. Idi ni yi ti o fi jẹ pe bi ọpọ tilẹ n ṣiṣẹ kakakara ati pẹlu ọpọlọ, nṣe ni o n nira si ni gbogbo igba fun wọn lati ri ounjẹ jẹ. Niwọn igba ti eyi si ri bẹ, nkan ti a nilo ni idasi Ọlọrun, ko ki i ṣe iṣẹ aṣekara si tabi ifẹhonuhan lọpọ yanturu si.

Wayi o, mi o wa fẹ ki o ṣi mi gbọ. Iṣẹ aṣekara ṣe koko, o si ni ipo tirẹ laye. Nitorina, ọrọ Ọlọrun gba wa niyanju lati ma ṣe iṣẹ karakara, ki a si ma ya ọlẹ. Ifẹhonuhan naa si tun wa ni ipo tirẹ ni aye, iyẹn nigba ti ko ba ki i ṣe ẹmi iṣọtẹ ni o wa lẹyin rẹ tabi ti ko ki i ṣe pe a ṣe e lati jẹ ki nkan ti o bajẹ tun buru si. Fun apẹrẹ, nigba ti Kora, Datani, Abiramu ati Oni fẹhonu han lodi si iṣẹdari Mose ati Aarọni, Ọlọrun ṣe idajọ awọn ati awọn ti o wa pẹlu wọn pẹlu iku kayefi. Ilẹ la ẹnu rẹ, o si gbe gbogbo wọn mi. Ki ni o fa? Wọn mura lati doju iṣedari awọn ẹni-ami ororo Ọlọrun ti o wa laarin wọn delẹ, ki wọn si kọ ẹyin gbogbo orilẹ-ede wọn si ifẹ Ọlọrun. (Wo: Numeri 16)

Amọ ṣa o, nigba ti awọn ọmọbinrin marun-un ọkunrin kan ti o n jẹ Selofẹhadi fẹhonu han si Mose pe ki wọn ma pa ile baba wọn ti nidi ogun pinpin, nitoripe ko ni ọmọkunrin, Ọlọrun ko ba wọn wi tabi fi iya jẹ wọn. Dipo bẹẹ, nṣe ni O fun wọn ni nkan ti wọn bere fun. Ki ni idi? Idi ni pe wọn ko lepa lati fa iṣedari Mose ya tabi lati ru awọn eniyan soke lodi si i. Dipo eyi, wọn kan fẹ ki o mọ wipe iyanjẹ ni yoo jasi ti a ba pa ile baba wọn ti ṣi ẹgbẹ kan nigba ti a ba n pin ilẹ-ileri. (Wo: Numeri 27:1-7)

Nitorina, ko buru ki a fẹhonu han lodi si nkan ti ko ṣiṣẹ tabi si nkan ti ko tọna nibi ti a ba wa. Aijẹbẹ, awọn alaṣẹ tabi awọn ti o wa ni ipo lati tun nkan ṣe kan le ro lọkan wọn pe nkan n lọ deede fun gbogbo eniyan. Fun apẹrẹ, ni asiko Eliṣa, iyan kan mu ni Isiraẹli ti o sọ diẹ lara awọn eniyan naa di ẹranko, ẹranko ti o n jẹ awọn ọmọ bibi inu wọn. Ọba wọn, niwọn igba ti o si n gbe ni ifọkanbalẹ ninu aafin rẹ, ko ba ma ti wa mọ nkan ti iyan yi ti n ṣe si awọn eniyan rẹ, ti ọkan ninu awọn obinrin orilẹ-ede naa ti o ti n jẹ awọn ọmọ-ọwọ wọn ko ba wa fẹhonu han si i. (Wo: 2Awọn Ọba 6:24-30)

Amọ ṣa o, bi o tilẹ jẹ wipe ifẹhonuhan arabinrin yi sọ ọba yi ji, o kan jẹ ki o mọ pe ohun ti jinna rere si iṣoro awọn eniyan rẹ ni. Ko yanju iṣoro naa. Ki a tilẹ sọ otitọ, ọba yi ko mọ ọna abayọ si iṣoro ti o wa nilẹ, nitoripe o kọja ọpọlọ rẹ. Nitorina, gbogbo nkan ti o ṣe ko kọja pe o wọ aṣọ ọfọ, o si tun leri si wolii ti o gbajumọ ju ni ilẹ naa ni asiko naa, iyẹn Eliṣa. Ki ni idi? Idi ni pe o ro wipe nitoripe wolii yi ko ṣipẹ too fun ilẹ naa ni nkan ṣe bajẹ to bi o ti ṣe bajẹ. (Wo: 2Awọn Ọba 6:30-31)

Nitorina, nibi ti ifẹhonuhan gan ba ti ṣe pataki, ko le fun awọn adari ni ọna abayọ si iṣoro ilẹ wọn tabi ti awọn eniyan wọn. Ti wọn ko ba mọ ohun ti o tọ lati ṣe lati ran awọn eniyan wọn lọwọ, ifẹhonuhan ko le yanju iṣoro yowu ti o ba wa nilẹ. Bi mo ti ṣe sọ tẹlẹ, ifẹhonuhan arabinrin yẹn ko fi opin si iyan ti o wa ni ilẹ Isiraẹli. Ṣugbọn o sọ ọba ji si pataki ki wọn ni idasi Ọlọrun. Ṣe Ọlọrun wa da si ọrọ wọn tabi ko da si? O da si nipa mimojuto gbongbo iyan ti ilẹ naa ni ati fifun wọn ni ọrọ̀ ki a to wi, ki a to fọ. (Wo: 2Awọn Ọba 7)

Nibakana, Ọlọrun le mojuto gbogbo gbongbo iyan ti a n ni iriri rẹ ni orilẹ-ede wa lọwọlọwọ yi, ki O si tun fun wa ni ọrọ̀ ki a to wi, ki a to fọ. A ko wa nilo lati duro de igba ti awọn eniyan ba to bẹrẹ si ni jẹ awọn ọmọ bibi inu wọn tabi ti ifẹhonuhan ti o n bi itajẹsilẹ ba gba ibi gbogbo kan ki awa ti a mọ ọn to bẹrẹ si ni ke pe fun idasi rẹ ni kiakia. Ṣugbọn awa melo gan ni a tilẹ ṣi gbagbọ pe Ọlọrun le yi nkan pada si rere fun wa ni orilẹ-ede yi? Kiki awa ti o ba gbagbọ ni ko ni dẹkun lati ma gbadura si i titi iṣẹ iyanu itusilẹ yoo fi ṣẹlẹ fun wa. Awọn naa si ni yoo tọ iyanu ti o n bọ yi wo, ti yoo si tun jẹ igbadun rẹ. Njẹ ki ọkan rẹ gba okun ki a ba le ka ọ mọ iye wọn, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni oṣu Ẹrẹna 2024 alaririn.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ìfẹ̀hónúhàn kò tó | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 03, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 44 Read More »