Má ṣe paámọ́ fún wọn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 28, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 52
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lẹkunrẹrẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o so oṣu Igbe ati Èbìbí 2024 pọ mọ ara wọn. Adura mi si ni pe, bi a ti ṣe n bẹrẹ ọsẹ naa, ki Ọlọrun ya ọ ya ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu anikanjọpọn ti ko jẹ ki O ri ọ lo lati fi didara rẹ han awọn ti o wa ni ayika rẹ. Amin.
Mo gba adura yi fun ọ nitoripe ọkan lara awọn idi ti Ọlọrun ko ṣe le lo ọpọ awọn eniyan rẹ, ti o n fi ojoojumọ jẹgbadun didara rẹ, lati fi oore-ọfẹ rẹ han awọn miran ti o wa ni ayika wọn ni pe wọn jẹ alanikanjọpọn. Ti awọn eniyan ba jẹ alanikanjọpọn, o ma n rọrun fun wọn lati tete gbagbe pe oore-ọfẹ Ọlọrun ti wọn n jẹgbadun kọja nkan ti ẹnikan ṣoṣo le e da jẹ tan. Ki a tilẹ sọ otitọ, oore-ọfẹ Ọlọrun kọja ohun ti gbogbo agbaye le jẹ tan. Oore-ọfẹ rẹ ko lodiwọn.
Nitorina, sisọ nipa oore-ọfẹ ati didara Ọlọrun fun awọn ti o wa ni ayika wa ko le di igbadun oore-ọfẹ yi ku ninu aye wa. Dipo bẹẹ, nṣe ni yoo tun ṣi ilẹkun fun wa lati jẹgbadun rẹ siwaju ati siwaju si. Ṣugbọn ọpọ wa ni o ma n gbagbe ara wọn sinu igbadun oore-ọfẹ ati didara Ọlọrun debi wipe wọn ko ni ranti mọ pe ọpọ ni ayika wọn ni awọn naa nilo iriri oore-ọfẹ ati didara rẹ, ki a ba a le tu wọn silẹ kuro lọwọ awọn nkan ti o n lepa lati pa wọn run, ki wọn si tun ba a le ma gbe igbe aye ti o nitunmọ. Ti a ko ba si wa tete sọji, ki a si ma ṣe ohun ti o tọ, nkan le bajẹ si fun wọn, ki awa naa pẹlu si sọ iwulo wa gẹgẹ bi awọn ti Ọlọrun fẹ ki wọn duro bi i imọlẹ ati iyọ ninu aye yi nu.
Wayi o, a ni apẹrẹ kan ti o daju ninu bibeli lori bi Ọlọrun ti ṣe fẹ ki a ma ṣe pẹlu igbadun oore-ọfẹ ati didara rẹ ti a n jẹ. Eyi wa ninu 2Awọn Ọba 6 ati 7. Bi akọsilẹ naa ti lọ, iyan kan ti o lagbara, ti o si tari awọn kan lati ma pa awọn ọmọ wọn jẹ, fi igba kan mu ni ilu Samaria. Igba ti ọba to wa gbọ eyi ni o to ranti pe Eliṣa, eniyan Ọlọrun, ma wa ni ilẹ naa ati wipe wiwa rẹ ni ilẹ naa yẹ ki o jẹ ki nkan yatọ.
Ni kukuru, Eliṣa sọtẹlẹ pe iṣẹlẹ iyanu ipese lọpọ yanturu kan yoo ṣẹlẹ ni ilẹ naa, eyi ti yoo jẹ ki gbogbo wọn gbagbe inira wọn ki ilẹ ọjọ keji to ṣu. Nkan si ri gẹgẹ bi o ti sọ wipe yoo ri. Lọna wo? Ki a ma deena pa ẹnu, Ọlọrun ṣẹruba awọn ọta wọn ti o fa iyan ti a n sọ yi pẹlu ariwo ẹgbẹ́ ogun nla kan ti wọn ko fojuri. Nitorina, wọn sa lọ, wọn si tun pa ohun gbogbo ti wọn ko wa lati gbogun ti ilu yi ti.
Ṣugbọn ko wa si ẹnikankan ninu ilu yi ti o mọ ohun ti o ṣẹlẹ, ayafi awọn adẹtẹ mẹrin kan ti wọn fi ẹmi wọn wewu lati wa ounjẹ lọ si ibi ti awọn ọta wọnyi tẹdo si lalẹ ọjọ kanna. Awọn ni o kọkọ kan ọpọ ounjẹ, aṣọ, fadaka, wura ati awọn meremere ọfẹ miran lojiji, eyi ti awọn ọta yi fi silẹ sẹyin nigba ti wọn n sa asala fun ẹmi wọn. Nitorina, wọn fi ara balẹ ni alẹ ọjọ yi lati ko ọpọ nkan meremere ti ipa wọn ka fun ara wọn. Ni alẹ ọjọ yi kanna, bi o tilẹ jẹ wipe adeẹtẹ ni wọn, wọn di ọlọro.
Amọ ṣa o, bi wọn ti wa n fo lati agọ awọn ọta wọn kan sinu omiran, ti wọn si gbe ohun yowu ti wọn fẹ, o kan dede sọ si iye wọn pe awọn ma ti fẹ di alanikanjọpọn. Bẹẹni, o sọ si wọn ni iye pe awọn nkan rere ti o wa ni ibi itẹdo awọn ọta wọn ma pọ ju nkan ti awọn mẹrẹrin nikan le da jẹ lọ — nkan ti o yẹ ki ẹnikọọkan ni ilẹ wọn pin ninu rẹ, ki wọn si tun jẹgbadun ni. Nitorina, wọn sọ awọn ọrọ yi si ara wọn: “Awa ko ṣe ohun rere. Oni yii jẹ ọjọ iroyin rere awa si paamọ ara wa.Ti awa ba duro titi di afẹmọjumọ, ijaya yoo jẹ ti wa. Ẹ jẹ ki a lọ ni ẹẹkan ki a lọ royin eyi fun awọn ile ọba.” (2Àwọn Ọba 7:9)
Wayi o, nikete ti wọn fi ohun ti o sẹlẹ to ọba leti ni gbogbo ilu jade lati lọ ko oniruuru ohun rere fun ara wọn. Lojiji ni gbogbo wọn si gbagbe awọn inira ti wọn ni iriri rẹ ni asiko iyan naa, ni ibamu pẹlu ọrọ eniyan Ọlọrun. Ka wa sọ wipe awọn adẹtẹ yi ko tete sọji lati ṣe ohun ti o tọ nkọ? Nṣe ni Ọlọrun ko ba dari ẹlomiran ti yoo royin ohun ti o sẹlẹ fun ọba si ibẹ. Ki wa ni o ro wipe ọba yoo ṣe si wọn fun iwa anikankọpọn wọn? O ṣeeṣe ki o da ẹjọ iku fun wọn.
Nikukuru, koko ọrọ mi ni pe ko yẹ ki a maa pa iyin rere oore-ọfẹ Ọlọrun ti a n jẹgbadun mọ fun awọn ti o wa ni ayika wa. Dipo bẹẹ, nṣe ni o yẹ ki a ṣa gbogbo ipa wa lati fi lọ wọn. Aijẹbẹ, bi mo ti ṣe sọ tẹlẹ, a le tipasẹ eyi bẹrẹ si ni din iriri didara rẹ ku ninu aye wa, ki Oun naa si tun wa gbe awọn miran dide lati ṣe ohun ti o yẹ ki a ti ṣe. Nigbanaa ni iyin ati ere ti o yẹ ki o jẹ ti wa yoo si wa lọ si ọdọ wọn. Nitorina, bẹrẹ si ni fi iyin rere didara Ọlọrun si ọ lọ awọn ni o wa ni ayika rẹ laitiju. Njẹ ki o ma fi ojoojumọ gba okun lati ọdọ Ẹmi Ọlọrun lati jẹ olododo ni ṣiṣe bẹẹ, ni orukọ Jesu. Amin.
Ki o ni ọsẹ ti o ga.
Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)


