Àkórí: Ní ìgbàgbọ́ ti ara rẹ nínú rẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òkúdù 30, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 9
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu ayọ ni mo ki ọ kaabọ si ọjọ ti o kẹyin oṣu yi ati si ọsẹ kini ninu oṣu Agẹmọ ti a ṣẹṣẹ fẹ wọ inu rẹ. Adura mi si ni pe ki o ni iriri ogo Ọlọrun ninu aye rẹ ni awọn ọna ti o kọja ero rẹ ni ọṣẹ yi ati ninu gbogbo oṣu tuntun ti o wa niwaju wa, ni orukọ Jesu. Amin.
Wayi o, mo fẹ gba ọ niyanju lori pataki ki o mu ibaṣepọ tikararẹ pẹlu Ọlọrun ni ọkunkundun, dipo eyi ti o o fi ma gbẹkẹle ibaṣepọ awọn miran pẹlu rẹ gẹgẹ bi ọna lati jẹgbadun rẹ. Mo si n pe akiyesi rẹ si eyi nitoripe ọpọ lo wa loni ti wọn pe ara wọn ni onigbagbọ ninu Kirisiti Jesu ṣugbọn ti o jẹ wipe ori igbagbọ awọn adari ijọ wọn ninu Ọlọrun tabi igbagbọ awọn kan ninu ẹbi wọn ninu Ọlọrun ni wọn gbojule fun ilọsiwaju tabi fun aabo wọn laye. Eyi si le ni ewu gidigidi fun wọn.
Fun apẹrẹ, a sọ eyi fun wa ninu bibeli nipa ọba Juda kan ti a n pe ni Joasi: “Joasi ṣe ohun ti o dara ni oju Oluwa ni gbogbo akoko Jehoiada alufaa.” (2Kironika 24:2) Ki ni idi ti ọkunrin yi ṣe ṣe ohun ti o tọ niwaju Ọlọrun ni asiko alufaa Jehoiada? Idi ni pe alufaa yii n dari rẹ ni ipa ọna ododo. A tilẹ ti sọ fun wa ninu akọsilẹ igbe aye rẹ pe alufaa yi gan an ni o yan awọn iyawo meji ti o fẹ fun un (2Kíróníkà 24:2).
Amọ sa o, lẹyin iku alufaa yi, nkan yi pada fun Joasi. O pa Oluwa ti, O si bẹrẹ si ni ṣe bi o ti ṣe wu u. Wo nkan ti a sọ ninu bibeli lori eyi:
“Lẹyin iku Jehoiada, awọn oniṣẹ Juda wa lati fi iforibalẹ wọn han si ọba. O si fesi si wọn. Wọn pa ile Oluwa ti, Ọlọrun baba a wọn. Wo si n sin awọn ere Aṣerah ati awọn oriṣa. Nitori ẹṣẹ wọn yii, ibinu Ọlọrun de sori Juda ati Jerusalẹmu. Bi o ti wu ki o ri, Oluwa ran awọn wolii si awọn eniyan lati mu wọn pada si ọdọ rẹ. Bi o tilẹ jẹ wi pe, wọn jẹrii nipa wọn, wọn ki yoo gbọ.” (2Kíróníkà 24:17-19)
Njẹ o ri bayẹn? Lẹyin iku Jehoiada, awọn adari ilẹ naa tan Joasi wọ inu ibọriṣa. O si tẹlẹ wọn. Ki ni idi ti o fi tẹle wọn? O tẹle wọn nitoripe oun funararẹ ko ni ibaṣepọ kankan ti o danmọran pẹlu Ọlọrun. Nitorina, o ṣe ohun yowu ti o ṣe fun Ọlọrun ṣaaju asiko yi nitori Jehoiada ni, ko ki i ṣe nitoripe o gbagbọ ninu Ọlọrun tabi ni ifẹ rẹ ni tootọ. Eyi tunmọ si pe o kan n ṣe oju aye ni. O kan n gbiyanju lati tẹ Jehoiada lọrun ni nitoripe oun ni ko jẹ ki wọn ti pa nigba ti o si jẹ ọmọ-ọwọ ati wipe oun ni o tọ ọ dagba, ti o si tun jẹ ki o ṣeeṣe fun lati di ọba. (Wo: 2Kíróníkà 22-23)
Amọ nigba ti ọkunrin yi ku, ti ko si si idi kankan fun lati ṣe ohunkohun lati tẹ lọrun mọ, o pa Ọlọrun ti, O si tẹle awọn miran wọ inu ibọriṣa lọ. Nitorina, a ke ijọba rẹ kuru, o si ku iku aitọjọ. Eyi, bi mo si ti ṣe sọ tẹlẹ, n fi han wa pe o ṣe pataki ki awa tikarawa ni ibaṣepọ tiwa pẹlu Ọlọrun. Eyi tunmọ si pe ma ṣe sin Ọlọrun, lọ si ipade sọọsi tabi ṣe bi eniyan mimọ nitoripe o kan fẹ tẹ awọn obi, ọrẹ, ọkọ, aya tabi ẹni ti o gba ọ ṣiṣẹ lọrun. Dipo eyi, nṣe ni ki o sin Ọlọrun, ki o si gbe igbe aye iwa mimọ nitoripe o ti mọ daju pe Oun ni ẹni naa ti O to gba ijọsin rẹ. Aijẹbẹ, asiko n bọ ti yoo han kedere si gbogbo awọn eniyan pe eke ni ọ lati ibẹrẹpẹpẹ.
Ni afikun, ti o ko ba ni ibaṣepọ ti ara rẹ pẹlu Ọlọrun, ti o si je wipe ojurere Ọlọrun ti o wa ninu aye awọn miran ni o gbojule, asiko le de ninu eyi ti o jẹ wipe awọn nikan ni igbagbọ wọn ninu Ọlọrun yoo le ṣiṣẹ fun, ko ni i le ṣiṣẹ fun ọ. Wo nkan ti Ọlọrun funrarẹ ni lati sọ fun wa lori eyi:
“Ọrọ Ọluwa tọ mi wa wi pe: “Ọmọ Eniyan bi orilẹ-ede kan ba dẹṣẹ si mi nipa iwa aiṣododo, emi yoo nawọ mi jade si wọn, lati gẹ ipese ounjẹ wọn, emi yoo ran iyan si wọn, emi yoo si pa eniyan ati ẹranko inu rẹ, bi awọn ọkinrin mẹta yii, Noa, Daniẹli ati Jobu tilẹ wa ninu wọn rẹ, kiki ẹmi ara wọn nikan ni wọn le fi ododo wọn gbala, Oluwa Olodumare wi.”” (Ìsíkíẹ́lì 14:12-14)
Mo mọ daju pe o ti ri alaye fun iku aitọjọ ti gbogbo awọn ọmọ Joobu ku ni ọjọ kan bayẹn (Joobu 1). Lati ibẹrẹpẹpẹ, igbagbọ baba wọn ninu Ọlọrun ni o n gbe wọn ro. Ṣugbọn igbagbọ rẹ ko le daabo bo wọn kuro lọwọ eṣu ni ọjọ ti o wa lati kọ lu ẹbi wọn; ohun nikan ni igbagbọ rẹ le da aabo bo. Ka wa lọ sọ wipe awọn naa mu Ọlọrun ni ọkunkundun bi oun ti ṣe mu ni ọkunkundun ni, o ṣeeṣe ki ọrọ naa ma lọ bi o ti ṣe lọ. Nitorina, ni igbagbọ ti ara rẹ ninu Ọlọrun dipo eyi ti o o fi ma gbojule igbagbọ awọn miran ninu rẹ. Nipa bayi, ti igbagbọ awọn miran ninu rẹ ba tilẹ kuna tabi rẹwẹsi, igbagbọ tirẹ ninu rẹ yoo le gbe ọ bori.
Ki o ni ọsẹ alarinrin.
Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)



