Àkórí: Kò ní gbàgbé rẹ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Agẹmọ 28, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 13
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ ti o so oṣu Agemọ ati oṣu Ògún 2024 papọ mọ ara wọn. Adura mi fun ọ ni pe ki Ọlọrun, ninu ọsẹ naa, sọ gbogbo awọn ti O ti yan lati ran ọ lọwọ ji lati bẹrẹ si ni ṣe ohun gbogbo ti O ran wọn lati ṣe fun ọ fun ọ. Amin.
Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ẹnikanṣoṣo ti ko ṣeeṣe ki O gbagbe wa tabi gbagbe lati mu ete rere rẹ ṣe fun wa ni Ọlọrun. Eniyan, fun oniruuru idi, le gbagbe wa tabi ki wọn gbegbe ileri ti wọn ṣe fun wa. Ṣugbọn Ọlọrun ko jẹ lailai gbagbe wa tabi gbagbe lati ṣe ojuṣe rẹ ni ṣiṣe ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu aye wa ni aṣepe. Iwo naa wo ohun ti O sọ fun wa nipasẹ wolii Aisaya lori eyi:
“Njẹ abiyamọ ha le gbagbe ọmọ ọmu rẹ ki o ma si ṣaanu fun ọmọ rẹ ti o ti bi? Bi o tilẹ jẹ pe oun le gbagbe Emi ki yoo gbagbe rẹ!” (Àìsáyà 49:15)
Njẹ o ri bayẹn? Bi o tilẹ jẹ wipe nigba miran abiyamọ le ṣiṣẹ gbagbe awọn nkan kan ti o yẹ ki o ṣe fun ọmọ rẹ, Ọlọrun ko ni lailai gbagbe lati ṣe ohun ti o tọ fun wa ni asiko ti o yẹ. Nitoripe ko si ni lailai gbagbe wa, a ko gbọdọ sọ ireti nu nitoripe nkan ko i ti ma a lọ deede fun wa bi a ti ṣe fẹ. Dipo eyi, nṣe ni o yẹ ki a ma fi igba gbogbo gbadura si pe ki O ṣe ohun gbogbo ti o jẹ ti wa laṣepe, ki O si tun fun ọkan wa ni okun lati ma a rin pẹlu rẹ pẹlu suuru, ki a ma ba doju iṣẹ rẹ ninu aye wa ru.
Lafikun, a tun gbọdọ ma gbadura pe ki Ọlọrun la ọna fun gbogbo awọn ti O ti yan lati ṣe awọn nkan ti yoo yọri si imuṣẹ ete rere rẹ fun aye wa lati ṣe ifẹ rẹ ninu aye wa. Idi si ni pe ko ki i ṣe gbogbo nkan ti Ọlọrun fẹ ṣe fun wa naa ni yoo ṣe funrarẹ. Awọn nkan kan wa ti o jẹ wipe nipasẹ awọn eniyan ni yoo gba ṣe wọn fun wa. Ti awọn nkankan ba si wa n yọ irufẹ awọn wọnyi lẹnu tabi ti awọn nkan ti aye yi ti gba ọkan wọn, wọn le ma ranti lati ṣe ohun ti Ọlọrun ran wọn lati ṣe fun wa ni asiko ti o tọ tabi ki wọn ma ranti rara.
Fun apẹrẹ, Ọlọrun ni o yan ijọye Farao kan ti Josefu ba pade ninu tubu lati ran an lọwọ lati jade ninu tubu naa ati lati tun ṣiṣẹ fun igbega rẹ ni Ijibiti. Lotitọ, ọkunrin ko mọ ni asiko naa pe Ọlọrun lo mu awọn mejeeji pade ara wọn tabi ọna ti Ọlọrun fẹ gba lo oun lati ran Josefu lọwọ. Ṣugbọn o wa lori ọkan rẹ lati ran an lọwọ, ti nkan ba ṣenu ire fun un. Eyi si n jẹ ki o ye wa pe ki awọn kan to le ran wa lọwọ gẹgẹ bi Ọlọrun ti fẹ ki wọn ṣe, nkan gbọdọ ma a lọ deede fun wọn. Aijẹbẹ, airoju tabi irẹwẹsi le ma jẹ ki wọn ri ti wa ro. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 40)
Nikukuru, nkan ma ṣenu ire fun ọkunrin yi, gẹgẹ bi Josẹfu ti fẹẹkan-tẹlẹri sọ fun. O jade kuro ninu tubu, a si tun da a pada si ipo giga ti o wa tẹlẹ ni Ijibiti. Sibẹsibẹ, fun awọn idi ti a ko mẹnuba ninu akọsilẹ iṣẹlẹ yi, o gbagbe Josefu patapata. Ki a tilẹ sọ otitọ, o gbagbe rẹ fun ọdun meji gbako.
Njẹ Josefu wa sọ ara rẹ di jatijati nitori eyi bi? Rara o! Ṣe o sọ ireti ninu Ọlọrun ati lori aye rẹ nu nitori eyi bi, pẹlu ero wipe ireti ominira oun ti sọnu? Rara o! Dipo eyi, nṣe ni o tẹsiwaju lati ma ṣe ohun ti o tọ ninu tubu ati lati mu suuru fun Ọlọrun. Nitorina, nigba ti asiko to, Ọlọrun, ti ko ki i lailai gbagbe awọn eniyan rẹ, mu ki awọn iṣẹlẹ waye ti o la ọna fun ọkunrin yi lati ranti Josefu ati lati ṣe awọn nkan ti o tọ lati mu jade kuro ninu tubu. Bi awọn ala pe Josefu yoo di ẹni giga ti Ọlọrun ti fifun un lati igba ewe rẹ wa si ṣe bẹrẹ si ni di mimuṣẹ leyi. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 41)
Nibakanna, Ọlọrun ko ni gbagbe iwọ naa. Nitorina, o le gbẹkẹle lati mu awọn ala didi ẹni-giga ati awọn ete rere rẹ fun aye rẹ ti O ti fi han ọ wa si imuṣẹ. Iwọ naa, bi Josefu, kan nilo lati mu suuru fun ni, ki o si tun tẹsiwaju lati ma ṣe ohun ti o tọ niwaju rẹ. Lara awọn nkan ti o tọ ti o si gbọdọ ma ṣe ni ki o ma gbadura si pe ki O la ọna fun gbogbo awọn ti O fẹ lo fun ọ lati ma ṣe ohun rere gbogbo ti o yẹ ki wọn ṣe fun ọ ni aidẹsẹ-duro. Njẹ ki Ẹmi Ọlọrun fun ọ ni okun lati fi awọn nkan wọyin sọkan ati lati ma fi ojoojumọ gbe igbesẹ ni ibamu pẹlu wọn, ni orukọ Jesu. Amin.
Ki o ni ọsẹ alarinrin.
Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)


