August 2024

Wọ́n le è ṣaájú rẹ nínú ìjọba náà | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 01, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 18

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu oṣu tuntun yi, iyẹn oṣu Òwewè 2024. Mo si gbadura pe ọkankan ninu awọn nkan ti o yẹ fun ibalẹ-ọkan ati igbega rẹ ko ni di pipamọ fun ọ ninu oṣu naa, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti n ṣe bẹrẹ oṣu yi, mo fẹ ran ọ leti owe Jesu Kirisiti Oluwa wa kan ti o lọ bayii:

“Ki ni ẹ ro nipa eleyii? Ọkunrin kan ti o ni awọn ọmọkunrin meji. O ṣọ fun eyi ẹgbọn pe, ‘Ọmọ, lọ ṣiṣẹ ninu ọgba ajara lonii.’ “O si da baba rẹ lohun pe, ‘Emi ko ni i lọ’, ṣugbọn nikẹyin o yi ọkan pada, o si lọ. Nigba naa ni baba yii tun sọ fun eyi aburo pe, ‘Lọ ṣiṣẹ ni oko.’ Ọmọ naa si sọ pe, ‘Emi yoo lọ, baba,’ ṣugbọn ko lọ rara. Ninu awọn mejeeji yii, ewo ni o ṣe ifẹ baba wọn? Gbogbo wọn si fohun ṣọkan pe, “Eyi ẹgbọn ni.” Jesu wi fun wọn pe, “Loootọ ni mo wi fun yin, awọn agbowo-ode ati awọn pansaga yoo wọ ijọba ọrun ṣiwaju yin.” (Mátíù 21:28-32)

Ki ni koko owe yi? Oun naa ni pe ko to ki a kan gba ninu ọkan wa lati ṣe ifẹ Ọlọrun; a tun gbọdọ tẹsiwaju lati ṣe e. Ti ko ba si wa jẹ wipe a n ṣe ohun ti a mọ, ti a si tẹwọgba gẹgẹ bi ifẹ Ọlọrun fun wa ni gbogbo abala aye wa, a ko yatọ si awọn ti ko gba Ọlọrun gbọ rara.

Bi a ti ṣe ri ninu owe yi, nigba ti baba yẹn sọ fun ọmọkurin rẹ akọkọ nipa ki o lọ ṣiṣẹ ninu ọgba ajara rẹ, ọdọmọkunrin yi sọ fun kedere pe oun ko ni lọ. Ki ni idi? A ko sọ fun wa. Amọ o ṣa di didan ki o ni idi tirẹ. Ṣugbọn nigba ti o ṣe diẹ si lọjọ yi kan naa, o ronu lori bi o ti ṣe kọ jalẹ lati gbọran si baba rẹ lẹnu, o si gba wipe nkan ti ko dara ni oun ṣe. Nitorina, o ronupiwada, o si lọ ṣe ohun ti baba rẹ pa a laṣẹ fun lati ṣe.

Ṣugbọn nigba ti baba yi ba ọmọkunrin rẹ keji sọrọ, ko ba a jiyan rara. Dipo bẹẹ, nṣe ni o sọ wipe, “Bẹẹni sà. Ma a lọ ṣiṣẹ ninu ọgba ajara yin, gẹgẹ bi ẹ ti ṣe pa a laṣẹ.” Amọ ko lọ rara lati ṣe ifẹ baba yi. Ki ni idi? A ko sọ fun wa. O ṣeeṣe ki o ni oniruuru awawi lati ma lọ. Ṣugbọn koko ibẹ naa ni pe ko lọ ṣe ifẹ baba rẹ, bi o tilẹ jẹ wipe o gba ni ibẹrẹ-pẹpẹ lati lọ ṣe e.

Wayi o, lẹyin igba ti o sọ owe yi tan, Jesu tẹsiwaju lati jẹ ki koko rẹ han si awọn adari ẹsin awọn Juu ti O sọ ọ fun. Ki si ni koko rẹ? Oun naa ni pe awọn ti wọn ka si ẹlẹṣẹ yoo ṣiwaju wọn wọ ijọba Ọlọrun. Ki ni idi? Idi ni pe bi o tilẹ jẹ wipe awọn mọ ifẹ Ọlọrun, ti wọn si tun n waasu nipa ifẹ rẹ, wọn ko ki i ṣe ifẹ rẹ. Ṣugbọn awọn ti wọn n pe ni ẹlẹṣẹ ati awọn alaiwulo eniyan n yipada kuro ninu ẹṣẹ wọn lati ṣe ifẹ Ọlọrun nipasẹ iwaasu Jesu. Nitorina, o di dandan ki wọn ṣiwaju wọn wọ ijọba Ọlọrun.

Nibakanna, a le ri ara wa gẹgẹ bi ẹni-bi-Ọlọrun ati ẹni ẹmi, nitoripe a n lọ si sọọsi deede, a n gbe bibeli kaakiri, a situn fi gbogbo igba sọ wipe, “Jesu loluwa.” Ṣugbọn ti a ko ba ṣe awọn nkan ti Ọlọrun fẹ ki a ṣe ninu aye wa ati ni awujọ wa, nṣe ni a kan n tan ara wa jẹ, ti a ko si yatọ si awọn ti ko gbagbọ rara. Amọ ti awọn ti a ro wipe ẹlẹṣẹ ti ko wulo rara ni wọn ba bẹrẹ si ni yipada lati ṣe ifẹ Ọlọrun ninu aye wọn, yoo ya wa lẹnu lọjọkan nigba ti a ba ri wipe wọn ti ṣiwaju wa wọ ijọba Ọlọrun.

Bawo wa ni yoo ti ṣe ri ni ara rẹ ni Ọjọ Oluwa ti o ba ri pe awọn kan ti o ko ro wipe wọn mọ nkankan nipa Ọlọrun tabi nipa ọna ododo ba wa ninu ijọba Ọlọrun nigba ti iwọ si wa ni ọrun apadi tabi ba wa ni ààyè ti o dara ju tirẹ lọ ninu ijọba Ọlọrun? Mo mọ wipe bi iru nkan wọnyi yoo ṣe ri lara kọja nkan ti a le e ro. Ṣugbọn bi yoo ti ri gẹlẹ niyẹn ti o ko ba fi ara rẹ jin lati ṣe ifẹ Ọlọrun tọkan-tọkan. Nitorina, dẹkun lati ma fi ẹsin ṣe boju-boju fun aigbọran si Ọlọrun lẹnu, ki o si bẹrẹ si ni ṣe ohun gbogbo ti o mọ gẹgẹ bi ifẹ rẹ fun aye rẹ. Mo si gbadura pe ki a fun ọ ni okun lati ṣe bẹẹ gẹgẹ, bi o ti ṣe n la oṣu yi ati eyi ti o ku ninu ọdun yi kọja lọ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Wọ́n le è ṣaájú rẹ nínú ìjọba náà | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 01, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 18 Read More »

Kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ogun 25, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 17

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o kẹyin oṣu yi, iyẹn oṣu Ogun 2024. Adura mi ni pe ki Ọlọrun ṣe ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu rẹ ninu oṣu naa ni aṣepe, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe n wọ inu ọsẹ tuntun yi, mo fẹ ran ọ leti pe ifẹ Ọlọrun fun ọ ni pe ki o ma fi gbogbo igba gbe iṣiṣẹ rẹ laye lati inu ẹkunrẹrẹ Ẹmi Ọlọrun ti o n gbe inu rẹ. Eyi tunmọ si pe, O n fojusọna pe ki o ma fi igba gbogbo sọrọ ati wuwa lati inu ẹkunrẹrẹ Ẹmi Mimọ. Nipa bayi, ohunkohun ti o ba jẹ jade laye rẹ yoo jẹ ohun ti yoo dun mọ Ọlọrun ninu ati ti yoo gbe awọn ti o wa ni ayika rẹ ro.

Wayi o, wo nkan ti Pọọlu sọ nipa eyi fun wa:

“Nitori naa ẹ ma ṣe jẹ alailoye, ṣugbọn ẹ maa moye ohun ti ifẹ Oluwa ja si. Ẹ ma si ṣe mu waini ni amupara, nitori eyi yoo pa yin run; ṣugbọn ẹ kun fun Ẹmi Mimọ. Ẹ si maa ba ara yin sọrọ ninu saamu, ati orin iyin, ati orin Ẹmi, ẹ maa kọrin, ki ẹ si maa kọrin didun ni ọkan yin si Oluwa. Ẹ maa dupẹ nigba gbogbo fun ohun gbogbo lọwọ Ọlọrun, ani Baba, ni orukọ Jesu Kirisiti Oluwa wa.” (Éfésú 5:17-19)

Ki ni nkan akọkọ ti Pọọlu sọ fun wa ninu ẹṣẹ yi? Ohun naa ni pe ki a ma jẹ omugọ tabi alailoye ṣugbọn ki a ni oye ifẹ Ọlọrun fun aye wa. Nitorina, nkan omugọ ni fun wa lati ma mọ ifẹ Ọlọrun fun aye wa. Bẹẹni, nkan omugọ ni fun wa lati ma ṣe awawi lori pe a ko mọ nkan ti Ọlọrun fẹ fun aye wa. Idi si ni pe a le mọ ifẹ rẹ fun aye wa ti a ba fẹ lati mọ ọn, ti a si tun n tiraka lati mọ ọn. Ti a ko ba si wa mọ ifẹ rẹ fun aye wa, ki a si ma gbe ni ibamu pẹlu rẹ, nṣe ni a o fi aye wa ṣofo.

Siwaju si, lẹyin igba ti o ti sọ pataki ki a mọ ifẹ Ọlọrun fun aye wa tan, Pọọlu tẹsiwaju lati sọ nkan kan fun wa nipa ifẹ Ọlọrun fun wa. Ki si ni eyi? Oun naa ni pe ifẹ Ọlọrun ni fun wa lati má mu ọti-waini ni amupara ṣugbọn lati kun fun Ẹmi Mimọ. Ki ni idi ti o fi fi mumu ọti-waini ni amupara we kikun fun Ẹmi Ọlọrun? Idi ni pe ti awọn eniyan ba yo tan, wọn a sọ ara wọn nu si abẹ iṣakoso waini, wọn a si bẹrẹ si ni sọrọ ati wuwa lati inu ẹkunrẹrẹ rẹ ninu wọn. Nibakan naa, ti awọn eniyan ba kun fun Ẹmi Ọlọrun, wọn a sọ ara wọn nu sabẹ iṣakoso rẹ, wọn a si bẹrẹ si ni sọrọ ati wuwa lati inu ẹkunrẹrẹ rẹ ninu wọn. Ki wa ni o fẹ, ṣe ki ọti-waini ma ṣe akoso rẹ ni tabi ki Ẹmi Ọlọrun ma ṣe akoso rẹ?

Ni kukukuru, ifẹ Ọlọrun ni pe ki o fi aye gba Ẹmi Ọlọrun lati di ọ mu ati lati ma ṣe akoso ohun ti o n sọ ati eyi ti o n ṣe. Bawo si ni o ṣe le ṣe eyi? O le ṣe e nipa kikun ara rẹ pẹlu ọrọ Ọlọrun. Idi si ni pe ọkan ni ọrọ Ọlọrun ati Ẹmi Ọlọrun. Ti o ba si kun ara rẹ pẹlu ọrọ rẹ, o di dandan ki o ma wuwa, sọrọ ati kọrin lati inu ẹkunrẹrẹ ọrọ rẹ ti o wa ninu rẹ pẹlu irọrun. Eyi si wa jasi pe ti o ko ba ki i wuwa, sọrọ tabi kọrin lati inu ẹkunrẹrẹ ọrọ Ọlọrun, o ko kun fun ọrọ rẹ niyẹn – nkan miran ni o kun fun.

Bi mo ti ṣe fihan tẹlẹ, ti awọn eniyan ba yo tabi kun fun ọti waini, wọn a ma sọrọ ati wuwa lati inu ẹkunrẹrẹ rẹ. Ṣugbọn ko ki i ṣe ọti waini nikan ni awọn eniyan le kun fun. Awọn eniyan le tun kun fun ikoro, ojukokoro, ibinu, ilara, igberaga tabi ifẹkufẹ. Ki a ma fọrọgun, ohun yowu ti wọn ba kun fun ni wọn yoo ma sọrọ, kọrin ati wuwa lati inu ẹkunrẹrẹ rẹ.

Wayi o, lotitọ awọn eniyan le sọ wipe awọn kun fun Ẹmi Ọlọrun. Ṣugbọn nkan ti wọn sọ wipe awọn kun fun kọ ni o ṣe pataki bikoṣe ohun ti aye wọn n gbe jade. Njẹ o tilẹ mọ wipe nipa wiwo abala bi nkan ti ṣe n lọ (sitetọsi) Wasáàpù, Fesibúùkù tabi awọn opo ẹrọ-ayelujara miran awọn kan, o le sọ nkan ti wọn kun fun? Bẹẹni, o le sọ boya ọrọ ati ifẹ Ọlọrun ni wọn kun fun tabi ibinu, irẹwẹsi, iporuru, ẹtanu, ifẹkufẹ, owu, ikunsinu tabi igberaga ni wọn kun fun. Ṣugbọn ni tirẹ, nkan ti o gbọdọ kun fun ni ọrọ Ọlọrun. Bi o ba si ṣe n kun ara rẹ pẹlu ọrọ rẹ, nṣe ni o ri wipe o n gbe igbe aye ti o buyi kun Ọlọrun ati eyi ti o n bukun fun ayika rẹ pẹlu irọrun.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ogun 25, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 17 Read More »

Àkórí: Onígbàgbọ́ tí kò dùn-ùn bá ṣepọ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ogun 18, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 16

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ògun 2024. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun kun ọkan rẹ pẹlu idunnu ti o ga fun un ati fun ijọba rẹ, bi a ti ṣe n bẹrẹ ọsẹ naa, ni orukọ Jesu. Amin.

Ọkan lara idi ti a ko fi ma ri ki ọpọ ma tikalara wọn tọ Jesu Oluwa wa fun igbala ni pe ọpọ ninu awa ti a pe ara wa ni Kirisitiẹni ni ara wa ko ya gaga si Ọlọrun ati si igbagbọ wa. Ara wa ko ya gaga lati ka ọrọ Ọlọrun tabi lati gbọ ọ. Ara wa ko ya gaga lati gbadura. Ara wa ko ya gaga lati kọrin ati lati jọ niwaju rẹ. Bẹẹ si ni ara wa ko ya gaga lati fi fun un. Ni kukuru, onigbagbọ ti ko dun un ba ṣepọ ni a jẹ.

Wayi o, ko si ẹni ti o fẹ wa nitosi awọn ti ara wọn ko ki i ya gaga. Ko si ẹni ti o fẹ wa ni arọwọto awọn ti ara wọn ko ki i ya gaga si aye wọn tabi si ohun yowu ti wọn ba n ṣe. Niwọn igba ti ọpọ wa ko si jẹ ẹni ti ara rẹ ya gaga lati ba gbe pọ, lati ba ṣiṣẹ tabi lati ba kẹkọ, awọn alaigbagbọ ti o wa ni ayika wa yo o yala gba ile-ọti tabi ile-ijo lọ dipo ki wọn wa pẹlu wa tabi ki wọn wa ninu awọn ipade ijọ wa. O ma ṣe o!

Ṣugbọn Ọlọrun ko ki i ṣe ẹni ti ara rẹ ko ya gaga lati ba gbe tabi lati wa pẹlu. A si ri ifarahan eyi ninu Jesu Kirisiti Oluwa wa, ẹni ti o jẹ aworan Ọlọrun ni gbogbo ọna. Ko ki i ṣe ẹni ti ara rẹ ko ya si eniyan lati ba gbe tabi lati wa pẹlu ni igba ti O wa ni orilẹ-aye yi. Ka awọn iwe iyinrere. Iwọ yoo si ri pe awọn ọmọ-ẹyin ko fi igba kankan ni asiko ikarisọnu pẹlu rẹ. Igba kan ṣoṣo ti inu wọn bẹrẹ si ni ba jẹ ni igba ti o han si wọn kedere pe a o gba kuro lọdọ wọn. Sibẹ O sọ fun wọn pe ki wọn banujẹ rara. Ki ni idi? Gẹgẹ bi O ti sọ, idi ni pe Ẹmi Mimọ yoo wa rọpo rẹ ninu aye wọn, lati ma gbe inu wọn, lati ma gbe pẹlu wọn ati lati ma gbe nipasẹ wọn. Nitorina, ko ni si idi fun wọn rara lati ma karisọ tabi lati ma gbe igbe aye ẹni ti ara rẹ ko ya gaga. (Wo: Jòhánù 14-16)

Ki wa gan ni idi ti ọpọ wa fi n karisọ, ti ara wa ko si tun ya gaga loni, bi o tilẹ jẹ wipe a n sọ pe a ni Ẹmi Mimọ ninu wa? Ki ni idi ti ara wa ko ṣe ya gaga si Ọlọrun, si ọrọ rẹ, si adura gbigba, si ififunni ati fun iṣẹ-isin ninu ijọ Ọlọrun? Ara wa a ma ya gaga lati wo awọn sinima ti awọn taye yi, lati gbọ orin aye, lati wa pẹlu awọn ọrẹ alaiwa-bi-Ọlọrun ati lati lọ si àjọyọ̀ awọn alaiwa-bi-Ọlọrun. Ṣugbọn ti ọrọ ba ti kan ibaṣepọ wa pẹlu Ọlọrun ati awọn eniyan rẹ, ikarisọ-sinu nikan ni a o ma ri ninu wa. Ki ni iṣoro wa gan?

Bi o ti ṣe han kedere, ẹmi ìlọ́wọ́wọ́ ti o wa ninu aye yi ni o ti gba wa mu. Ẹmi kan naa yi ni o pọn ijọ Ọlọrun ti o wa ni Laodesia igba aye bibeli loju, ti o si sọ wọn di ẹni-ikaanu, oloṣi, talaka, afọju ati ẹni-ihoho ninu ẹmi. Ki ẹ si wa ma wo o, ẹmi ika yi ko ni sọ pe ki a ma lọ si awọn ipade ijọ mọ, tabi pe ki a ma gbadura mọ, tabi pe ki a ma gbọ ọrọ Ọlọrun mọ tabi pe ki a ma fifun ni mọ. Ṣugbọn yoo jẹ ki a ma ṣe awọn nkan wọnyi ni ọna ti ko nitunmọ ati ti ko wu ni lori debi wi pe a ko ni jẹ ere kankan nipa ṣiṣe wọn. (Wo: Ìfihàn 3:14-22)

Wo o, bi a ti ṣe fi han wa ninu bibeli, awọn eniyan ko ki di ẹni-ọtun ati ẹni-igbega lati ọwọ Ọlọrun nitoripe wọn kan tọ ọ wa. Dipo bẹẹ, wọn a ma di ẹni-ọtun ati ẹni-igbega nitoripe wọn tọ ọ wa pẹlu ọkan ti o mura giri lati ba a gbe ati lati di alabukunfun nipasẹ rẹ. Nkan ti mo n sọ ni pe kiki awọn ọkan ti o n fi imura-giri ṣafẹri Ọlọrun ati awọn nkan ti o ti pese silẹ fun wọn nikan ni yoo gbadun rẹ lotitọ, ti yoo si tun le fa awọn miran wa si ọdọ rẹ. (Wo: Hébérù 11:6)

Nitorina, ti aye rẹ ko ba ma fa awọn miran si ọdọ Jesu Kirisiti Oluwa wa, a jẹ wipe ara rẹ ko ya gaga si rara tabi ki o jẹ wipe itara ati idunnu rẹ si i ko to. Bi o ti wa ri pẹlu awọn ọmọ ijọ Laodesia, iwọ wa ni abẹ ewu ki Oluwa kọ ọ silẹ gẹgẹ bi eke onigbagbọ. Adura mi si pe nigba ti a ba duro niwaju Oluwa ni ọjọ-ologo ni, ki a ma ṣe kọ ọ silẹ gẹgẹ bi eke ọmọ Ọlọrun, ni orukọ Jesu. Ṣugbọn o ni lati gbadura si Ọlọrun lọwọlọwọ yi pe ki O sọ ohun gbogbo ti o ti di oku niti itara rẹ ati idunnu rẹ si i ati si ijọba rẹ ji, ki aye rẹ ba a le ma jo bi ina fun titi asiko rẹ lori ilẹ-aye yi yoo fi wa si opin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Àkórí: Onígbàgbọ́ tí kò dùn-ùn bá ṣepọ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ogun 18, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 16 Read More »

Fi ara rẹ jìn fún ìtọ́ni rẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ogun 11, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 15

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu yi. Mo si gbadura pe ki Ẹmi Ọlọrun jẹ ki ọkan rẹ ma fi ojoojumọ fi ara rẹ jin fun itọni Ọlọrun, ki a ba a le dari rẹ sinu ohun ti o dara julọ ti O yan fun ọ laye. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, Ọlọrun fẹran wa to bẹẹ gẹẹ ti ko fi fẹ ki a ṣi ẹṣẹ gbe laye yi. Ko fẹ rara pe ki a fi asiko wa ṣofo lati ma a le ojiji ati awọn nkan ti ko lere lori kiri. Ṣugbọn a o le ojiji ati awọn nkan ti ko lere, ti a ko ba ni itọni rẹ, nitoripe bibeli sọ wipe, “Emi mọ Oluwa wi pe aye eniyan ki i ṣe ti ara rẹ, ki i ṣe fun eniyan lati gbe igbesẹ ara rẹ.” (Jeremáyà 10:23)

Njẹ o ri bayẹn? Aye wa ko ki i ṣe ti wa, a ko si wa ni ipo lati tọ iṣiṣẹ ara wa. Ta wa ni o wa ni ipo lati tọ iṣiṣẹ wa laye yi? Ọlọrun ẹlẹda wa ni! Ṣe O si wa nifẹ lati ṣe eyi? Bẹẹni, O nifẹ lati ṣe e. Bibeli tilẹ sọ fun wa pe ko ki i ṣe pe Ọlọrun nifẹ si itọsọna wa ni ipa ọna ti o tọ nikan, nṣe ni ọkan rẹ tilẹ wa lori ṣiṣe bẹ ẹ.

Amọ ṣa o, a gbọdọ fi ara wa jin fun itọni rẹ sinu ohun ti o dara julọ ti O fẹ fun wa, ki a si ma ya alagidi tabi ẹni ti o gbọn loju ara rẹ. Aijẹbẹ, nṣe ni a o dari ara wa sinu afonifoji ojiji iku. Ti eyi ba si wa ri bẹ ẹ, iku ati iyagan nikan ni a le reti, ti a ba fi asiko ṣofo ki a to kesi Ọlọrun fun aanu rẹ. (Wo: Sáàmù 32:8-9)

Wo Lọọti, fun apẹrẹ. Nigba ti o wa pẹlu Aburahamu, awọn mejeeji ko jẹ lọ si ibikibi ti Ọlọrun ko ba dari wọn si. Ṣugbọn ni ọjọ kaana ti o fi Aburahamu silẹ, o bẹrẹ si ni ṣe idari ara rẹ. O bẹrẹ si ni yan ni ibamu pẹlu ohun ti o ri ati nipasẹ ọgbọn ara rẹ. Awọn nkan ti o si yan wa pada jẹ ki o padanu ọrọ ati iyawo rẹ ati ki idibajẹ ba ẹbi rẹ. (Jẹ́nẹ́sísì 13&19)

Nitorina, ma ṣe tun lailai gbiyanju lati dari ara rẹ. Dipo bẹẹ, jẹ ki Ọlọrun dari rẹ. Iwọ yoo si jẹ ki O dari rẹ, niwọn igba ti o ba gbagbọ pe O mọ nkan ti O n ṣe ati wipe ko le lailai dari rẹ sinu iparun bikoṣe si ibi iṣerere ti O ni lọkan fun ọ. Lotitọ, ni awọn igba miran, Ọlọrun le dari rẹ lọ si eti Okun Pupa. Nkan ti mo n sọ ni pe awọn asiko le wa ti Ọlọrun le fi ọ si aarin Okun Pupa ati ogun Farao. Ṣugbọn niwọn igba ti O ba ti tẹsiwaju lati ma a tẹle, pẹlu ọkan wipe O mọ nkan ti O n ṣe, ko si ọkankan ninu Okun Pupa tabi ogun Farao ti yoo le di ọ lọwọ lati bẹ ibi ti o yẹ ki o de laye.

Ọna wo wa ni Ọlọrun yoo gba dari mi, niwọn igba ti o jẹ wipe n ko le ri i? Nikukuru, ọna kan gbogi ti Ọlọrun ma n gba dari awọn ọmọ rẹ ni nipasẹ akọsilẹ ọrọ rẹ. Bẹẹni, O tun ma n dari wọn lẹkọọkan nipasẹ iran, ala, isọtẹlẹ tabi awọn angẹli. Ṣugbọn ko ni lailai dari wọn lati ṣe ohunkohun ti o tako akọsilẹ ọrọ rẹ. Idi si ni yi ti o fi gbọdọ ma fi ojoojumọ fi ara rẹ jin fun ọrọ rẹ ati adura gbigba. Niwọn igba ti o ba ti n ṣe eyi, o le fi ọwọ sọya pe ọna ti o yẹ ki o gba laye yi ko tun ni lailai dojuru fun ọ mọ. Idi si ni pe Ọlọrun yoo ri daju pe a dari rẹ si oju ọna ti o yẹ ki o tọ.

Nitorina, fi ara rẹ jin fun ọrọ Ọlọrun ati adura gbigba lojoojumọ. O si di dandan ki Ọlọrun dari rẹ sinu ohun gbogbo ti o darajulọ fun aye rẹ.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Fi ara rẹ jìn fún ìtọ́ni rẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ogun 11, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 15 Read More »

Àkórí: Àlàáfià fún ìṣerere | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ogun 04, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 14

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu idunnu ni mo ki ọ kaabọ sinu oṣu miran ninu ọdun yi, iyẹn oṣu Ògún 2024. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun fun ọ ni alaafia ni gbogbo ọna, ni gbogbo igba ati lori ohun gbogbo ti o jẹ tirẹ ninu oṣu naa. Amin.

Ki ni idi ti o ṣe ṣe pataki ki a ni alaafia ninu wa ati ni gbogbo ayika wa? Idi pataki kan fun eyi ni pe alaafia m n gbe iṣerere ati ìgbáyégbádùn larugẹ. Nigba ti awọn eniyan ba wa ni alaafia ninu ọkan wọn, wọn le fi ara balẹ ronu, ki wọn si ni awọn ala lati ṣe nkan ti o ga. Lafikun, ti awọn eniyan ba ni alaafia ni gbogbo ayika wọn, wọn yoo le dari gbogbo okun wọn lati mu awọn ala wọn ṣẹ.

Ṣugbọn ti ọkan awọn eniyan ba poruru, ti ko si si ibalẹ-ọkan fun wọn, bi anfaani tilẹ wa fun wọn lati gbe awọn nkan ti o ga ṣe, ibẹru ko ni jẹ ki wọn ṣe amulo awọn anfaani yi. Fun apẹrẹ, Pọọlu sọ eyi nipa asiko ranpẹ kan ti o le ni Tiroa: “Ṣugbọn nigba ti mo de Tiroa lati waasu iyinrere Kirisiti, ti mo si ri wi pe Oluwa ti ṣilẹkun fun mi, Sibẹ emi ko ni alaafia lọkan mi, nitori ti emi ko ri Titu arakunrin mi nibẹ. Nitori idi eyi ni moṣe dagbere fun wọn, mo si rekọja lọ si Makedonia.” (2Kọ́ríntì 2:12-13)

Njẹ o ri bayẹn? Bi o tilẹ jẹ wipe anfaani ti o ga wa fun apọsiteli yi lati waasu iyinrere ni ilu yẹn, ko le e ṣe amulo anfaani naa. Ki ni idi? Ko ni ibalẹ-ọkan. Nkankan n yọ ọ lẹnu. Ki si ni nkan naa? Oun naa ni pe ko ri Titu, alabaṣiṣẹpọ rẹ, nibẹ. O wa ṣeeṣe ki awa naa ṣe bakan naa pẹlu, ti a ba ba ara wa ni irufẹ ipo kanna. A le jẹ ki anfaani ti o jọju lati gbe nkan nla ṣe tabi lati jẹgbadun ara wa lọ, ti ara ẹni ti a fẹran kan ko ba ya tabi ti ẹni naa ba wa ni ipo iyọnu.

Lafikun, ti idarudapọ ba yi wa ka, bi a tilẹ ni awọn ala ati amuyẹ ti o ga, a le e ma le mu nkankan ti o nitunmọ jade lati ipasẹ awọn ala ati amuyẹ naa. Ọpọ ni o si ti ku pẹlu awọn ala ti o ga ti wọn ni nitoripe ibi ti wọn gbe ko ni alaafia ti o peye to lati fi aye gba ilọsiwaju. Bẹẹ si ni pẹlu, bi a ba tilẹ ri awọn ala wa mu wa si imuṣẹ ni agbegbe ti o kun fun idarudapọ ati iyọnu, a le ma le jẹgbadun iṣẹ ọwọ wa bi o ti ṣe tọ ni ibẹ.

Nitorina, ki a ni amuyẹ ti o ga ati ala ti o ga ni ibi ti ko ti si alaafia dabi ki a ma ni nkankan rara ni. Ki a tilẹ sọ otitọ, o le ma jẹ nkan ti o mọgbọn wa fun wa lati ma ronu tabi la ala lati ṣe nkan ti o ga ni ibi ti ko ti si alaafia. Fun apẹrẹ, nkan ti Ọlọrun sọ fun ọkunrin kan ti a n pe ni Baruku, ẹni ti o jẹ akọwe fun Jeremaya, ni eyi: “Ṣe iwọ yoo wa ohun rere fun ara rẹ? Nitori naa, ma ṣe wa wọn. Emi yoo mu ibi wa si ori awọn eniyan gbogbo ni Oluwa wi. Nibikibi ti o ba lọ ni emi yoo jẹ ki o sa asala ẹmi rẹ ni alaafia.” (Jeremaya 45:5)

Njẹ o ri bayẹn? Ọlọrun sọ fun Baruku lati ma ronu lati gbe ohun giga kankan ṣe fun ara rẹ ni ilẹ Juda ni asiko yẹn. Ko gbọdọ ronu lati kọ ile, bẹrẹ okowo tabi fẹ aya fun ara rẹ. Ki ni idi? Ajalu n bọ lori ilẹ naa. Ajalu ti o si n bọ yoo pa gbogbo orilẹ-ede naa run, yoo si tun le gbogbo awọn ti o wa nibẹ danu. Amọ ṣa o, Ọlọrun ṣe ileri lati pa ọkunrin yi mọ nibikibi ti o ba lọ.

Ṣe o wa ri bayi pe alaafia ṣe pataki gidigid fun ilọsiwaju ati igbayegbadun. Idi si ni yi ti a ṣe gbọdọ ma fi igba gbogbo gbadura, bi a ti ṣe paṣẹ fun wa ninu Iwe Mimọ, fun alaafia Ọlọrun lati jọba ninu aye wa ati ni gbogbo ayika wa. Nitorina, mo tun gbadura fun ọ lẹẹkan si, bi a ti ṣe bẹrẹ oṣu tuntun yi, pe ki Ọlọrun jẹ ki alaafia rẹ ti o kọja oye eniyan jọba ninu aye rẹ, ni ayika rẹ ati lori ohun gbogbo ti o jẹ tirẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni oṣu Ògún 2024 ti o ga.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Àkórí: Àlàáfià fún ìṣerere | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ogun 04, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 14 Read More »