September 2024

Ebi àti ìpòngbẹ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 29, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 22

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu idunnu ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o so oṣu Òwewè ati Ọ̀wàrà 2024 pọ mọ ara wọn. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ma fi igba gbogbo jẹ ki ọkan rẹ pongbẹ fun un, ki o ba a le e mọ ọn bi o ti ṣe yẹ ki o mọ ọn ati ki o ba a le gbadun ohun rere gbogbo ti O ni ni ipamọ fun ọ. Amin.

Bibeli sọ eyi fun wa nipa ọna lati mọ Ọlọrun ni ọna ti o peye ati lati gba itẹlọrun lọwọ rẹ laye yi: “Alabukun-fun ni awọn ti ebi n pa, ti oungbẹ n gbẹ nitori ododo, nitori wọn yoo yo.” (Mátíù 5:6) Ki ni eyi n sọ fun wa? Oun naa nipe bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun fẹ fi ara rẹ han wa, ti O si tun fẹ mu ete rere rẹ fun aye wa ṣẹ, kiki awa ti ebi n ba pa wa, ti oungbẹ si tun n gbẹ wa fun un ati fun awọn nkan ti O ni fun wa ni yoo pada gba itẹlọrun lẹkunrẹrẹ. Awọn ti ebi ko pa wọn, ti oungbẹ ko si tun gbẹ wọn fun un n fi han pe awọn ko nilo rẹ. Nitorina, bi wọn tilẹ n fi ẹnu jẹwọ rẹ gẹgẹ bi Ọlọrun wọn, gbogbo nkan ti wọn le reti lati jẹgbadun lọwọ rẹ ko ju awọn ibukun gbogbogboo rẹ lọ.

Ti o ba wo inu bibeli, iwọ yoo ro wipe awọn ti o mọ Ọlọrun daradara, ti wọn si tun jẹgbadun Ibukun rẹ ni awọn ọna ti ko wọpọ ni awọn ti o fi han pe ebi ati oungbẹ fun un n pa awọn gidigidi. Fun apẹrẹ, a sọ eyi fun wa nipa Mose ati awọn ọmọ Isiraẹli: “O fi ọna rẹ han fun Mose, iṣẹ rẹ fun awọn ọmọ Isiraẹli.” (Sáàmù 103:7) Njẹ o ri bayi pe iyatọ ti o ga wa lara bi Ọlọrun ti ṣe ba Moṣe lo pọ ati bi O ti ṣe ba awọn ọmọ Isiraẹli lo pọ? Gbogbo nkan ti awọn ọmọ Isiraẹli n ri ko ju awọn iṣẹ iyanu Ọlọrun ti a ṣe fun wọn lọ. Wọn ko ni oye idi ti O ṣe n ṣe awọn iṣẹ yi tabi nkan ti wọn le ṣe lati jẹ ki awọn iṣẹ yi waye.

Ṣugbọn Mose le sọ idi ti Ọlọrun ṣe ṣe ohunkohun ti O ṣe fun awọn ọmọ Isiraẹli. O si tun le sọ idi ti Ọlọrun ṣe un wọn ni awọn ofin ti O fun wọn pẹlu. Idi si ni pe oun mọ ọna Ọlọrun. Bawo lo ṣe wa mọ ọna Ọlọrun? Ṣe nitoripe Ọlọrun pe, ti O si tun ran an lati lọ tu orilẹ-ede Isiraẹli silẹ kuro ni Ijibiti ni? Rara o! Dipo eyi, titoripe ebi n pa a, oungbẹ si tun n gbẹ ẹ lati mọ Ọlọrun ati lati mọ ọna rẹ ni o ṣe ribẹ. Iwọ naa wo diẹ lara awọn adura rẹ si Ọlọrun:

“Bi iwọ ba ni inu didun pẹlu mi, kọ mi ni ọna rẹ, ki emi ki o le mọ ọ, ki n si le maa wa oju rere rẹ pẹlu. Ranti wi pe orilẹ-ede yii eniyan rẹ ni.” (Ẹ́kísódù 33:13)

“Mose si wi pe, “Nisinsin yii fi ogo rẹ han mi.”” (Ẹ́kísódù 33:18)

Njẹ o ri bayẹn? Ko tẹ Mose lọrun lati kan jẹ adari orilẹ-ede Israẹli. Bẹẹ si ni ko tẹ lọrun lati kan jẹ oniṣẹ-iyanu. Dipo bẹẹ, o tun fẹ mọ Ọlọrun ni ọna ti o peye, ki o si tun ri ogo rẹ. Ki ni idi? Idi ni pe o mọ wipe fun igba diẹ naa ni oun fi le jẹ adari orilẹ-ede Israẹli ati oniṣẹ-iyanu. Nigba ti o ba ya, yoo ku, yoo si fi ohun gbogbo silẹ. Ṣugbọn ti o ba mọ Ọlọrun, ti o si ri ogo rẹ, yoo ma a ba a gbe titi lailai. Niwọn igba ti o si jẹ wipe nkan ti ebi n pa a fun, ti oungbẹ si n gbẹ ẹ fun ni eyi, Ọlọrun fi tẹ lọrun.

Tun wo Dafidi naa. Ki ni idi ti o ṣe mọ Ọlọrun bi o ti ṣe mọ ọn, bi o tilẹ jẹ wipe ko ki i ṣe alufaa tabi wolii bi ti Mose? Idi ni wipe ebi n pa oun naa, oungbẹ si tun n gbẹ ẹ fun un. O tilẹ fi igba kan sọ wipe, “Ọlọrun o, tọkantọkan ni mo n ṣafẹri rẹ; oungbẹ rẹ n gbẹ ọkan mi, ara mi si n fa si ọ.” (Wo: Sáàmù 63:1)

Nitorina, ti ebi ba n pa awa naa, ti oungbẹ si n gbẹ wa fun Ọlọrun, dipo fun awọn ere ori ẹrọ mohunmaworan, ẹfẹ, ariya ati awọn nkan miran ti ko ki ṣaba gbe aye eniyan ro, Oun yoo tẹ wa lọrun pẹlu ẹkunrẹrẹ rẹ, aye yoo si ri ogo rẹ ninu wa. Otitọ ti o si wa wa nibẹ ni pe idi ti pupọ-julọ lara wa ko ṣe ma ni iriri ogo Ọlọrun ninu aye wa bi o ti ṣe tọ ni pe ebi ati oungbẹ wa fun un ko to. Bawo wa ni a ṣe le fihan pe ebi n pa wa ati pe oungbẹ n gbẹ wa fun gidigidi? A le fihan nipa fifi itara lọ fun ọrọ rẹ, adura gbigba ati ibaṣepọ pẹlu awọn ọmọ rẹ ni aisimi.

Ranti pe bi o tilẹ jẹ wipe arugbo ati olukọ ti o ga ni Isiraẹli ni Nikodemu, o rẹ ara rẹ silẹ, o si wa kọ ẹkọ lọdọ Jesu Oluwa ni alẹ ọjọ kan (Jòhánù 3:1-2). Ki ni idi? Oungbẹ n gbẹ ẹ lati mọ Ọlọrun si. Emi naa si wa ranti pe, ni awọn ọdun melokan sẹyin, mo ṣe debi wipe mo n ya awọn iwe Kirisitiẹni ati awọn akasilẹ iwaasu lọwọ awọn ti ko tilẹ ki i ṣe ọmọ ijọ mi, nitoripe mo fẹ mọ Ọlọrun si i. Ọpọ igba ni mo si ma n ji ni ọganjọ oru lati ka awọn iwe yi tabi lati gbọ awọn akasilẹ iwaasu yi, ki n ba le da wọn pada fun awọn ti o ni wọn ni asiko. Ki ni a n pe eyi? Ebi ati ipongbẹ fun Ọlọrun! Ṣe o wa lere lori tabi ko ni? O lere lori.

Nitorina, ti ebi ba n pa iwọ naa, ti oungbẹ si n gbẹ ọ fun Ọlọrun, o di dandan ki o mọ ọn, ki o si tun jẹgbadun rẹ kọja ireti rẹ. Ṣugbọn ti ebi ko ba pa ọ, ti oungbẹ ko si tun gbẹ ọ fun un, awọn nkankan wa ti o ko le lailai mọ nipa rẹ tabi jẹgbadun lati ọwọ rẹ. Nitorina, gbadura pe ki O ma fi ojoojumọ ji ebi ati ipongbẹ otitọ fun ninu rẹ lọna ti o ga, ki o ba le ni iriri ẹkunrẹrẹ rẹ.

Kí ó ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ebi àti ìpòngbẹ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 29, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 22 Read More »

Ya ara rẹ sọ́tọ̀ fún ìyanu | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 15, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 20

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo fi tayọtayọ ki ọ kaabọ sinu ọsẹ kẹrin ninu oṣu Owewe 2024. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun ma fi ojoojumọ ọsẹ naa ṣe ọ yẹ pẹlu ohun gbogbo ti o nilo lati ri gbogbo ipese rere rẹ fun ọ gba ati lati jẹgbadun wọn. Amin.

Wayi o, pẹlu nkan ti a ri ninu Iwe mimọ, awọn ti o ma n ri ipese Ọlọrun fun aye wọn gba ni ọna ara ṣaba ma n jẹ awọn ti o ṣetan lati ya ara wọn sọtọ kuro laarin awọn ero. Bẹẹni, wọn ma n ṣaba jẹ awọn ti o ṣetan lati ṣe ohun ti awọn miran ko ni ṣe tabi ohun ti ẹru n ba wọn lati ṣe. Nitorina, Ọlọrun yoo rekọja awọn miran lati ṣe agbayanu iṣẹ iyanu fun wọn.

Fun apẹrẹ, Jesu sọ eyi fun wa nipa Namani ati opo Sarefati:

“Ṣugbọn mo wi fun un yi nitootọ, opo pipọ ni o wa ni Isirẹli nigba ti ọrun fi ṣe ni ọdun mẹta oun oṣu mẹfa, nigba ti iyan nla fi mu ka ilẹ gbogbo; Ko si si ẹnikan ninu wọn ti a ran Elija si, bi ko ṣe si obinrin opo kan ni Sarefati, ilu kan ni Sidoni. Adẹtẹ pupọ ni si n bẹ ni Isirẹli nigba wolii Eliṣa; ko si si ọkan ninu wọn ti a wẹnumọ, bi ko ṣe Namani ara Siria.” (Lúùkù 4:25-27)

Njẹ o ri bayẹn? Bi o tilẹ jẹ wipe adẹtẹ pọ ni Isirẹli ni asiko Eliṣa (a tilẹ mẹnuba mẹrin lara wọn ninu bibeli ti wọn yọju ni asiko iyan kan ti o mu ni ilẹ naa ni igba Eliṣa), ko ri akọsilẹ pe o wo ọkankan ninu wọn san. Ki ni idi? Ṣe ko fẹ wo wọn san ni? Rara o! Iba kuku dun mọ ninu lati wo wọn san. Ṣugbọn ọkankan ninu wọn ko ri bi ẹni ti o ni agbara Ọlọrun to lati wo wọn san. (Wo: 2Àwọn Ọba 7)

Amọ ṣa o, nigba ti Namani ara Siria gbọ nipa rẹ lati ẹnu ọdọmọdebirin ẹru kan, o rin irin ajo lati orilẹ-ede rẹ lati wa pade rẹ. Ko wa wo iye ti eyi yoo naa tabi wahala ti irinajo naa yoo ko si. Ko tilẹ wo ipo rẹ gẹgẹ bi balogun tabi bi nkan ti ri ti o jẹ wipe orilẹ-ede Isiraẹli wa ni abẹ akoso orilẹ-ede rẹ ni asiko naa. Dipo eyi, nṣe ni o rẹ ara rẹ silẹ, ti o si tọ ọ wa. Nigba ti o si ṣe bẹẹ, o ri agbayanu iṣẹ-iyanu iwosan. A wo ẹtẹ rẹ san. Ki si ni idi? Idi naa ni pe o ṣe ohun ti awọn adẹtẹ miran bi tirẹ ko gbe igbesẹ lati ṣe. O ya ara rẹ sọtọ fun iṣẹ iyanu. (Wo: 2Àwọn Ọba 5)

Opo Sarefati nkọ? Ki ni idi ti Ọlọrun fi re gbogbo awọn opo ti o wa ni Isiraẹli kọja lati wa a ni asiko iyan ọdun mẹta ati aabọ ti o waye ni igba Elija? Idi ni wipe o ya ara rẹ sọtọ bi oninudidun ọlọrẹ. Arabinrin yi ṣetan lati pin ounjẹ rẹ ti o ṣẹku pẹlu eniyan Ọlọrun, nitoripe Ọlọrun sọ fun pe ki o ṣe bẹ ẹ. Nitori eyi, yatọ si pe a bọ oun ati ọmọ rẹ pẹlu ounjẹ ni asiko iyan yi, o tun gba ọmọ rẹ pada laaye lati inu oku nigba ti iku wa lati ji ọmọ naa mọ lọwọ. (Wo: 1Àwọn Ọba 17)

Ki wa ni koko gbogbo ọrọ yi? Ohun naa ni pe ti a ko ba ṣetan lati ya ara wa sọtọ kuro laarin awọn eniyan pẹlu itara nini, ninu adura gbigba, ninu ṣiṣe aṣaro ninu ọrọ Ọlọrun ati jijẹwọ rẹ ati ninu ififunni, awọn iṣẹ iyanu kan wa ti a ko ni lailai ri laye yi. Njẹ o wa ṣetan lati ya ara rẹ sọtọ lati ri awọn iṣẹ iyanu ti ko wọpọ gba lọwọ Ọlọrun bi?

Ki a ma fọrọgun, Ọlọrun ko ni mu wa ni tipatipa lati ṣe ohunkohun lati ya ara wa sọtọ kuro laarin awọn eniyan lati le ri gba lọwọ rẹ. Amọ ti a ba ṣe bẹ ẹ, o di dandan ki O re ọpọ kọja lati ya wa lẹnu. Adura mi si ni pe ki ọkan rẹ gba okun lati bẹrẹ si ni ṣe awọn nkan ti yoo ya ọ sọtọ fun awọn iṣẹ iyanu ti ko wọpọ, ni orukọ Jesu. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ya ara rẹ sọ́tọ̀ fún ìyanu | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 15, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 20 Read More »

Ìgbàgbọ́ àti sùúrù | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 15, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 20

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lailai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ kẹta ninu oṣu Òwewè 2024. Adura mi ni pe ki Ọlọrun ma fi ojoojumọ fun ọkan rẹ pẹlu okun lati ma fi igba gbogbo rin pẹlu rẹ ninu suuru, ki o ba a le ri ohun rere gbogbo ti O fẹ ki o gba gba lẹkunrẹrẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, igbagbọ ninu Ọlọrun nikan kọ ni a nilo lati ri nkan gba lọwọ rẹ; a tun nilo suuru lati ri nkan gba lọwọ rẹ. Ki a ti lẹ sọ otitọ, awọn nkankan wa ti a ko le lailai ri gba ati jẹ igbadun lọwọ Ọlọrun ti ko ba ṣe pe a n ba a rin pẹlu rẹ pẹlu suuru. Ki ni idi? Ọkan gbogi laara idi ni pe nkan ti o wa lọkan Ọlọrun koja ki O kan ṣe nkan fun awọn eniyan rẹ tabi lati fun wọn ni nkan; nkan miran ti O tun ma n mumu laya rẹ ni bi wọn yoo ṣe jẹ igbadun lẹkunrẹrẹ ohunkohun ti O ba fun wọn tabi ṣe fun wọn.

Nitorina, ki Ọlọrun to ṣe nkankan tabi fun awọn eniyan rẹ ni nkan, yoo kọkọ ri daju pe Oun ti mojuto ohunkohun ti ko ni jẹ ki nkan naa fi ogo fun un nipasẹ aye wọn tabi ti yoo di wọn lọwọ lati jẹgbadun nkan naa lẹkunrẹrẹ. Eyi si wa le gba asiko diẹ. Ti oye eyi ko ba wa ye awọn eniyan rẹ pe o yẹ ki wọn ma a mu suuru ninu ibaṣepọ wọn pẹlu rẹ, ọpọ nkan rere ti o yẹ ki wọn ri gba lọwọ rẹ ni wọn yoo ṣaba ma padanu.

Idi si ni yi ti bibeli ṣe sọ fun wa pe, “Ki ẹ ma ṣe di onilọra, ṣugbọn alafarawe awọn ti wọn ti ipa igbagbọ ati suuru jogun awọn ileri.” (Hébérù 6:12) Njẹ o ri bayẹn? A nilo igbagbọ ati suuru lati ri gba lọwọ Ọlọrun. Nitorina, bi a tilẹ mọ daju wipe Ọlọrun fẹ ki nkankan jẹ ti wa, a nilo ju pe ki a kan gbagbọ pe O le fun wa ni nkan naa; a tun gbọdọ fi suuru duro lati ri nkan naa gba lọwọ rẹ.

O wa ṣeni laanu pe ọpọ awa onigbagbọ ni a ko fẹ ni suuru rara lati ri gba lọwọ Ọlọrun. A ro wipe niwọn igba ti a ba ti ni igbagbọ ninu Ọlọrun, ti a si n ṣe ifẹ rẹ, ohun rere gbogbo ti O fẹ ki a ni ni yoo bẹrẹ si ni wa si ọdọ wa funra wọn. Ṣugbọn eyi ko ki i fi gbogbo igba ri bẹ. Rinrin ninu igbagbọ ninu Ọlọrun ati ṣiṣe ifẹ rẹ dabi iṣẹ ọgbin ni. Ko si agbẹ ti yoo fun irugbin rẹ loni, ti yoo si ma a reti ikore lẹsẹkẹsẹ. Dipo bẹ ẹ, nṣe ni yoo fi suuru mojuto awọn nkan ti o gbin titi di asiko ikore.

Wayi o, bayẹn gan ni rinrin ninu igbagbọ pẹlu Ọlọrun ati ṣiṣẹ ifẹ rẹ ti se ri. A nilo lati tẹsiwaju lati ma rin pẹlu rẹ ati lati ma ṣe ifẹ rẹ titi asiko ikore. Amọ igba wo ni asiko ikore. A ko le sọ. Igbakigba ti o ba jẹ naa ni. Lotitọ, awọn agbẹ, nipasẹ iriri, le sọ asiko ikore awọn nkan oko wọn. Ṣugbọn awa ko le sọ igba ti a o kore awọn ileri Ọlọrun fun aye wa tabi awọn ere fun ṣiṣe ifẹ rẹ. Nitorina, ọrọ Ọlọrun sọ eyi fun wa:

“Nitori naa ẹ ma ṣe gbe igboya yin sọnu, eyi ti o ni ere nla. Nitori ẹyin ko le ṣe alaini suuru, nitori igba ti ẹyin ba ti ṣe ifẹ Ọlọrun tan ki ẹyin le gba ileri naa.” (Hébérù 10:35-36)

Njẹ o ri bayẹn? Ma ṣe gbe igboya rẹ ninu Ọlọrun ju sọnu nitori pe o ko i ti ri ikore awọn ileri rẹ fun ọ. Dipo eyi, nṣe ni ki o kọ suuru ni ṣiṣe ifẹ rẹ titi ohun gbogbo ti o yẹ ki o jẹ tirẹ yoo fi tẹ ọ lọwọ. Bẹẹ ni, o nilo lati kọ suuru ni gbigbadura, ni ṣiṣe aṣaro ninu ọrọ Ọlọrun ati ninu jijẹwọ rẹ ati ninu rinrin ninu ododo. Bi o si ṣe n ṣe eyi, ohun gbogbo ti o yẹ ki jẹ tirẹ di dandan ki o jẹ tirẹ nipa oore-ọfẹ Ọlọrun, ti o ko ba rẹwẹsi.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ìgbàgbọ́ àti sùúrù | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 15, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 20 Read More »

Ìwọ fẹ́, kí o sì tún gbọ́ràn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 08, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 19

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu ayọ ti o ga ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ keji ninu oṣu Òwewè 2024. Adura mi si ni pe ki a mu ọkan rẹ le nisisiyi ati ni gbogbo igba lati le fẹ fun ara rẹ ohun ti Ọlọrun fẹ fun ọ ati lati le fi fi ara rẹ balẹ lati lọ fun nkan naa. Amin.

Ọkan lara awọn nkan ti a fi han wa leralera ninu Iwe Mimọ ni pe ko to ki Ọlọrun fẹ ki eniyan ni nkan; awa naa gbọdọ fẹ lati ni ohun yowu ti O fẹ ki a ni. Yatọ si iyẹn, a tun gbọdọ ṣetan lati ṣe ohun yowu ti O ba fẹ ki a ṣe lati le ni ohun yowu ti O ba fẹ ki a ni. Aijẹbẹ, ti ko ba jẹ wipe a ba ṣaanu fun wa, a ko ni ni ohun ti O fẹ ki a ni.

Idi si wa niyi ti Ọlọrun ṣe sọ eyi fun wa lati ipasẹ Àìsáyà: “Ti ẹyin ba fẹ, ti ẹ si gbọrọ, ẹyin yoo si jẹ ojulowo adun ilẹ naa.” (Àìsáyà 1:19) Pẹlu nkan ti Ọlọrun sọ nibiyi, ki ni ohun naa ti O fẹ ki a ni? Awọn nkan ti o dara ju ni bi ti a n gbe ni. A wa gbọdọ jẹ ki o ye wa pe Ọlọrun nibiyi ko ma sọrọ nipa awọn nkan ti o dara ju ni ibi ti a n gbe lọwọlọwọ yi. Idi si ni pe awọn nkan ti o dara ju ni ibi ti a n gbe lọwọlọwọ yi le ma dara to fun wa wa tabi fun ẹbi wa. Ṣugbọn awọn nkan ti o dara ju ti Ọlọrun ti gbin si ibẹ, ti o le ma ti han kedere si ẹnikẹni, di dandan ki o kọja bẹ ẹ fun wa.

Bawo wa ni a ṣe le fọwọgan awọn nkan ti o dara ju ti Ọlọrun ti gbin si ilẹ wa fun rere wa? Akọkọ, bi a ti ṣe fi han wa nipasẹ Aisaya, a gbọdọ fẹ lati ni awọn nkan yi i. Eyi tunmọ si pe a ko gbọdọ ṣetan lati tẹba ti awọn nkan ti o kere si nkan ti o dara julọ ti Ọlọrun fẹ fun wa tabi ṣetan lati jẹ ki wọn tẹ wa lọrun. Eyi ko wa jasi pe ki a ma lẹmi ọpẹ fun awọn nkan ti Ọlọrun ti fẹkan-tẹlẹri fi fun wa tabi ṣe fun wa. A gbọdọ ma fi ọpẹ fun Ọlọrun fun ohun gbogbo ti O ti ṣe fun wa ati ti O n ṣe ninu aye wa. Ṣugbọn bi a ti ṣe n fi ọpẹ fun fun awọn nkan ti a n jẹgbadun lati ọwọ rẹ, a tun gbọdọ ma tẹsiwaju lati nawọ gan ohun rere gbogbo ti O fẹ ki a ni. Aijẹbẹ, nṣe ni a o pada gbe igbe aye ti ko koju-oṣuwọn to irufẹ igba aye ti O fẹ ki a gbe.

Iwọ naa wo nkan ti a sọ ninu Iwe Mimọ nipa Joṣua nigba ti opin ọjọ aye rẹ sumọ etile: “Nigba ti Joṣua si darugbo ti ọjọ ori rẹ si pọ jọjọ, Oluwa sọ fun un pe, “Iwọ ti darugbo pupọ, bẹẹ ni ilẹ si ku lọpọlọpọ fun yin lati gba.”” (Jóṣúà 13:1) Njẹ o ri bayẹn? Lẹyin igba ti Joṣua ti di ogbo tan, Ọlọrun si tun ni ilẹ lọpọlọpọ fun lati gba. Iyẹn jasi pe ko ti ni ẹkunrẹrẹ iriri awọn nkan ti o dara julọ ti Ọlọrun fẹ ki o ni ni asiko yẹn. O wa ṣeni laanu pe ara rẹ ko mokun to mọ ni asiko naa lati nawọ gan gbogbo nkan ti Ọlọrun fẹ ki o ni. O ma ṣe o!

Nitorina, titi di ọjọ ogbo wa, Ọlọrun ko ni dẹkun lati ma ṣi oju wa lati ri awọn ipese rere rẹ fun wa. Bawo wa ni yoo ti ṣe dara to, ti a ba le nawọ gan gbogbo wọn, ki a si jẹgbadun wọn? Nikukuru, ọna kan ti eyi ṣe le ṣẹlẹ ni ki a fẹ, ki a si tun ni itara lati ni gbogbo awọn nkan wọnyi. Aijẹbẹ, gẹgẹ bi i Joṣua, igba ti awa naa ba di ogbo tan, ti ara wa ko si mokun to mọ lati ma sare kaakiri ni a o too maa ri gbogbo awọn nkan ti a ko ba ti gba ati jẹgbadun lati ọwọ Ọlọrun. Ṣugbọn o le e ti wa pẹju ni igba yẹn. Mo wa gbadura pe ko ni lailai pẹ ju fun ọ lati ṣe idamọ ipese Ọlọrun ti o dara ju fun ọ ati lati nawọ gan an. Amin.

Nkan ekeji ti Ọlọrun sọ wipe a gbọdọ ṣe lati le jẹ igbadun awọn ipese rẹ ti o dara julọ fun wa ni ilẹ wa ni ki a gbọran. Eyi tunmọ si pe a gbọdọ fi ara wa jin lati ma tẹle aṣẹ rẹ lori bi a ti ṣe le gba ipese rẹ ti o dara julọ fun wa ati bi a ti ṣe le gbadun rẹ. Aijẹbẹ, bi a tilẹ nifẹ si lati ni ipese rẹ ti o dara julọ fun wa, a ko ni le e nawọ gan an ati gbadun rẹ. Ti a ba si tilẹ nawọ gan awọn ipese rẹ ti o dara julọ fun wa nipa titẹle imọ tara wa, o di dandan ki nkan yowu ti a ba tipasẹ eyi ri fi ìkorò sinu aye wa. Nitorina, nikẹyinkẹyin a ko ni le e jẹ igbadun rẹ bi o ti ṣe tọ.

Wayi o, adura mi ni pe ki o ma kan jẹ wipe wa ri ipese Ọlọrun ti o dara julọ fun ọ ni orilẹ-ede yi gba, bi o ti wu ki nkan ri ninu orilẹ-ede naa, amọ ki o tun jẹ wipe wa a jẹ igbadun rẹ lẹkunrẹrẹ. Ṣugbọn iwọ naa gbọdọ fẹ lati ri gba ati lati jẹ igbadun rẹ, ki o si tun jẹ ẹni ti o n gbọran si gbogbo aṣẹ Ọlọrun si ọ.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ìwọ fẹ́, kí o sì tún gbọ́ràn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 08, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 19 Read More »