November 2024

Ó le è ṣé ní àṣepé | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀pẹ 01, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 31

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kiristi Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu oṣu ti o kẹyin ọdun yi, oṣu Ọ̀pẹ 2024. Adura mi ni pe ki Ọlọrun ṣe ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu rẹ lọdun yi ni aṣepe, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, ẹnikan le bere pe, “Ṣe Ọlọrun lotitọ si le ṣe ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu aye mi lọdun yi ni aṣepe, pẹlu wipe ẹyin ni aye mi wa ni ọpọlọpọ ọna?” Bẹẹni, O le ṣe e. Ko si bi aye rẹ ṣe rẹyin to tabi bi o ṣe jina to si imuṣẹ awọn erongba rẹ fun ọdun yi, Ọlọrun si tun le ṣe ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu rẹ ni aṣepe.

Bibeli sọ wipe, “Awa mọ wipe ninu ohun gbogbo Ọlọrun n ṣiṣẹ fun ire awọn ti o fẹran rẹ, ani fun awọn ẹni ti a pe gẹgẹ bi ipinnu rẹ.” (Róòmù 8:28) Eyi tunmọ si pe bi ohun gbogbo ti o n ṣẹlẹ ni ayika rẹ tilẹ n ṣiṣẹ lodi si ilọsiwaju, ibalẹ-ọkan ati ohun rere yowu ti o ni lọkan lati ni, nṣe ni Ọlọrun n ṣiṣẹ fun ire rẹ lati ṣe ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu rẹ ni aṣepe. Ta wa ni o le da Ọlọrun duro ti O ba n ṣiṣẹ? Ko si ẹni na ti o le da a duro ayafi iwọ nikan.

Wo o, ko si agbara naa laarin gbogbo nkan ti a da ti o to bẹẹ lati da Ọlọrun duro lati ṣe ọ ni rere tabi lati ṣe ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu aye rẹ ni aṣepe. Amọ iwọ le da a duro. Lọna wo? Akọkọ, o le e da a duro nipaṣẹ aigbagbọ. Awọn ọmọ Isiraẹli ti Mose ko jade lati Ijibiti da Ọlọrun duro lati fun wọn ni Ilẹ-Ileri nipasẹ aigbagbọ wọn. Ko ki i ṣe eṣu ni o da a duro lati fun wọn ni ilẹ ti o n ṣan fun wara ati fun oyin yi. Awọn ni wọn da a duro lati fi fun wọn. Nibakana, ti awa naa ko ba ma a fi gbogbo igba fi igbagbọ wa ninu Ọlọrun han nipa ṣiṣiṣẹ lori ọrọ rẹ, a le da a duro, di i lọwọ tabi fa ifasẹyin fun lori ṣiṣe ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu wa ni aṣepe.

Ekeji, o le di iṣẹ Ọlọrun lati ṣe ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu aye rẹ ni aṣepe nipasẹ aimoore. Jesu, ni igba kan, wo awọn adẹtẹ mẹwa kan ṣan kuro ninu ẹtẹ wọn. Ṣugbọn ọkan ṣoṣo ninu wọn, eyi ti o si jẹ ara Samaria, ni o pada wa lati dupẹ lọwọ rẹ. Ẹnikan ṣoṣo yi naa ti o pada wa lati dupẹ lọwọ rẹ si wa ni o tun gba ọrọ ibukun fun isọdipipe ati aṣepe lati ẹnu rẹ. Awọn yoku ko ri i gba. (Wo: Lúùkù 17:11-19)

O wa ṣeni laanu pe, ọpọ ninu aye loni ni Ọlọrun ko ti ṣe ọrọ aye wọn ni aṣepe nitoripe awọn naa, gẹgẹ bi awọn adẹtẹ mẹsan ni i, ya alaimore. Kiki igba ti wọn ba nilo nkan lọwọ Ọlọrun ni wọn a ma sọkun, yira nilẹ ati lọ si ọdọ awọn adari ijọ wọn lore-koore fun amọran ati adura. Amọ ti wọn ba ti bẹrẹ si ni ni iriri didara rẹ ninu aye wọn, nṣe ni wọn yoo ma da jẹ igbadun rẹ. Wọn ko ni dupẹ lọwọ Ọlọrun lọna ti o peye tabi mọ riri awọn ti O lo fun wọn. Ba wo wa ni wọn ṣe fẹ ni iriri aṣepe iṣẹ rẹ ninu aye wọn?

Siwaju si, a tun ri awọn ti o n di iṣẹ Ọlọrun ninu aye wọn lọwọ tabi ti o n da a duro nipasẹ ẹṣẹ. Jesu, ni asiko kan, sọ fun ọkunrin kan ti O wo san pe ki o maṣe dẹṣẹ mọ. Ki ni idi? Idi naa ni ki nkan ti o buru ju eyi ti o ṣẹlẹ si tẹlẹ ma ba a tun ṣẹlẹ si i. Eyi jasi pe bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun, nipasẹ iwosan ti ọkunrin yi ṣẹṣẹ rigba lọwọ Jesu, ti bẹrẹ iṣẹ imupadabọsipo ninu aye rẹ, ti ko ba dẹkun lati ma a dẹsẹ, iṣẹ ti Ọlọrun n ṣe ninu aye rẹ ko ni jẹ aṣepe. Dipo eyi, nṣe ni iṣẹ naa yo dawọduro. Tani o wa mọ nkan ti eyi yoo jasi fun un? (Wo: Johanu 5:14)

Ni kukuru, mo fi awọn nkan wọnyi han ọ ki o ba a ye ọ pe awa nikan ni o le di Ọlọrun lọwọ lati ma ṣe ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu aye wa ni aṣepe. Niwọn igba ti eyi si ri bẹ ẹ, bi a ti ṣe n wọ awọn ọjọ ti o kẹyin ọdun yi, nṣe ni ki a ya ara wa ya ohunkohun ti o le di Ọlọrun lọwọ tabi da a duro lati ṣe gbogbo nkan ti o ni i ṣe pẹlu wa ni aṣepe. Bẹẹni, nṣe ni ki a ya ara wa ya aigbagbọ, aimoore ati oniruuru ẹṣẹ. Bi a si ṣe n ṣe eyi, oore-ọfẹ Ọlọun yoo ma a ṣan ninu aye wa lalai ni idiwọ fun aṣepe ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu wa. Amin.

A kú Oṣù Ọ̀pẹ 2024 o.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ó le è ṣé ní àṣepé | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀pẹ 01, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 31 Read More »

Láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 24, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 30

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o pari oṣu Belu 2024. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun ma fi ojoojumọ fun ọ ni okun lati jẹ olotitọ si ninu ọsẹ naa ati ni gbogbo iyoku ọdun aye rẹ. Amin.

Jesu Oluwa wa sọ wipe, “Ṣugbọn ẹni ti o ba foriti i titi de opin, oun naa ni a o gbala.” (Mátíù 24:13) Ki ni eyi tunmọ si? Lakọkọ, o tunmọ si pe irin igbagbọ wa pẹlu Ọlọrun gbọdọ jẹ lati ibẹrẹ de opin. Lafikun, o tun tunmọ si pe iṣẹ-isin wa fun Ọlọrun gbọdọ jẹ lati ibẹrẹ de opin. Aijẹbẹ, a ko ni le jẹ alabapin ogo ayeraye rẹ. Siwaju si, ko ni si ere kankan fun wa lati ọdọ Ọlọrun fun iṣẹ yowu ti O ba fun wa ti a ko ṣe ni aṣetan.

Ki ni idi ti Ọlọrun fun mu Enọku wọ inu ogo rẹ lọ, ti ko si jẹ ki o tọ iku wo? Idi ni pe o ṣe deede ninu irin igbagbọ rẹ pẹlu rẹ lati ibẹrẹ de opin. Ọkunrin yi ko bẹrẹ si ni ba Ọlọrun rin titi o fi pe ẹni arun-din-laadọrin ọdun. Ṣugbọn lẹyin igba ti o ti bẹrẹ si ni ba a rin, ko tun fi igba kankan dẹkun lati ma a ba a rin, bẹ ẹ si ni ko lalai yipada si ọtun tabi si osi. Nṣe ni o kan tẹsiwaju lati ma a fi otitọ ba a rin fun ọdunrun ọdun, titi a fi mu wọ inu ogo rẹ lọ. (Jẹ́nẹ́sísì 5:21-23)

Lafikun, ki ni idi ti Ọlọrun fi ri Nọa ati idile rẹ gbala kuro ninu ikun omi ti o pa gbogbo nkan alaaye run ni asiko wọn? Idi naa ni pe o ṣe olododo ni kikan ọkọ ti Ọlọrun ni ki o kan. Ko ṣiṣẹ lori kikan ọkan naa fun igba diẹ ki o si dawọ iṣẹ duro. Dipo bẹẹ, nṣe ni o fi ara rẹ jin lati kan ọkọ naa titi iṣẹ rẹ fi pari.

Njẹ o wa rọrun fun Nọa lati ṣe eyi? Rara o! Owo ara rẹ ni ọkunrin yi ma na lati kan ọkọ yi. Siwaju si, owo ara rẹ ni o ma tun na lati pese ounjẹ ti awọn idile rẹ ati gbogbo awọn ẹranko ati ẹyẹ ti yoo wa pẹlu rẹ ninu ọkọ naa yoo ma a jẹ fun gbogbo asiko ti wọn yoo fi wa ninu ọkọ yi. Sibẹsibẹ, o fi suuru ṣe nkan ti Ọlọrun ni ki o ṣe titi o fi pari rẹ. Ọlọrun naa si wa fi suuru duro de titi o fi pari ọka naa nitoripe O mọ wipe ọkan rẹ wa lori ki o pari iṣẹ naa. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 6; 1Pétérù 3:20)

Nitorina, a le reti pe ki Ọlọrun mu suuru fun ẹnikẹni ti o ba fi ara rẹ jin lati fi ododo ba a rin ati lati fi ododo ṣe iṣẹ rẹ lati ibẹrẹ de opin. Ẹni ti ko ba jẹ olotitọ ninu ifarajin rẹ si Ọlọrun ni O le ma mu suuru fun. Dipo eyi, nṣe ni yoo wa ẹlomiran ti yoo fi rọpo rẹ, bi O ti ṣe si Ọba Sọọlu.

Ni kukuru, nkan ti mo n sọ ni pe ẹni ti yoo pada wọ inu ogo Ọlọrun lẹyin aye yi ni ẹni naa ti o jẹ olotitọ ni biba a rin lati ibẹrẹ de opin, ko ki i ṣe ẹni ti o kọ ọ silẹ. Awọn eniyan le ni oniruuru idi lati kọ Oluwa silẹ. Fun apẹrẹ, Dẹma kọ ọ silẹ nitoripe o fẹ aye yi. Awọn miran si le kọ ọ silẹ nitoripe awọn oniwaasu kan ṣẹ wọn tabi nitoripe wọn woye wipe O lọra lati ṣe awọn nkankan fun wọn. Idi yowu ti wọn le ni lati kọ ọ silẹ, wọn ko ni wọ inu ogo rẹ. (Wo: 2Tímótì 4:10)

Lafikun, kiki awọn ti o ba n polongo ọrọ Ọlọrun lati ibẹrẹ de opin, ti wọn n gbadura lati ibẹrẹ de opin ati ti wọn n ṣe iṣẹ yowu ti O fun wọn lati ibẹrẹ de opin ni yoo gba ere lọwọ rẹ. Awọn ti o ba jẹ ki iṣẹ rẹ su wọn, ti wọn si pa a ti ko ni gba ere lọwọ rẹ. Wọn le lo irẹwẹsi, inunibini, ailowo-lọwọ tabi nkan miran gẹgẹ bi awawi lati ma pari iṣẹ ti O fun wọn. Ṣugbọn niwọn igba ti wọn ko ba ti pari iṣẹ ti a fun wọn, ki wọn ṣi pari rẹ daradara, ko ni si ere kankan fun wọn.

Nitorina, ti o ko ba fẹ ki gbogbo nkan ti o ti ṣe pẹlu Ọlọrun ati fun un ja si pabo, pinnu lọkan rẹ pe o ko ni pa irin igbagbọ rẹ tabi iṣẹ isin rẹ ninu ijọba rẹ ti fun idi kankan. Dipo eyi, nṣe ni iwọ yoo ma a ba a rin, ti o o si ma sin-in pẹlu otitọ titi de opin. Njẹ ki o ma fi ojoojumọ gba okun lati ṣe bẹ ẹ gẹgẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 24, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 30 Read More »

Ayọ́kẹ́lẹ́ balé-ọlá-jẹ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 17, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 29

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu ayọ ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Belu 2024. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun ya aye rẹ ya ohunkohun ti o le ma fi idibajẹ sinu rẹ, ki Satani ma ba a le ri ọ lo lati fi idibajẹ sinu ijọ Ọlọrun ni ọna kankan. Amin.

Lara awọn nkan ti awọn apọsiteli igbaani sọ fun wa pe ki a kiyesi ninu ijọ ni awọn ọjọ ikẹyin yi ni awọn ayọkẹlẹ bale-ọla-jẹ. Awọn wo wa ni ayọkẹlẹ bale-ọla-jẹ? Awọn kan ninu ijọ ma ni, awọn ti o jẹ wipe awọn nan n sọ pe ti Kirisiti ni awọn n ṣe, bi awa yoku, ṣugbọn ti o jẹ wipe nṣe ni wọn n yọkẹlẹ fi idibajẹ sinu aye awọn eniyan Ọlọrun lati sọ wọn di alaiwulo fun Ọlọrun ati lati fi aaye silẹ fun Satani lati ṣiṣẹ laarin wọn.

Wayi o, lara awọn nkan ti awọn eniyan wọnyi ma n lo lati yọkẹlẹ fi idibajẹ sinu ijọ ni ẹkọ-eke ati ẹtan. Wo nkan ti Peteru sọ lori eyi:

“Ṣugbọn awọn wolii eke wa laarin awọn eniyan naa pẹlu, gẹgẹ bi awọn olukọni eke yoo ti wa laarin yin. Wọn yoo yọ́lẹ̀ mu ẹkọ odi ati egbe tọ yin wa, ani ti yoo ṣẹ́ Oluwa ti o ra wọn pada, wọn o si mu iparun ti o yara kankan wa sori ara wọn. Ọpọlọpọ ni yoo si maa tẹle ọna itiju wọn, ti wọn yoo si mu ki ọna otitọ di isọrọ-odi-si. Ninu iwa wọbia wọn, awọn ẹlẹkọ-odi wọnyi yoo maa rẹ ẹ yin jẹ nipa itan asan. Idajọ ẹni ti ko falẹ lati igba yii wa ati iparun wọn ti ko si toogbe.” (2Pétérù 2:1-3)

Njẹ o woye pe awọn adari ijọ ni awọn ti Peteru n sọrọ nipa nibiyi? Nitorina, ti a ba n sọrọ nipa awọn ayọkẹlẹ bale-ọla-jẹ ninu ijọ, ko yọ awọn adari ijọ silẹ. Adari ijọ le ma a yọkẹlẹ fi idibajẹ sinu aye awọn ọmọ Ọlọrun nipa ẹkọ-eke, awọn ẹkọ ti o n gbe iwa-wọbia, iṣekuṣe ati iṣọtẹ larugẹ. Fun apẹrẹ, arabinrin kan ti fi igba kan ri sọ fun mi pe pasitọ oun sọ fun oun pe ara ojuṣe ẹmi oun ni ki o ma ṣe tọju rẹ pẹlu ibalopọ. Ki si ni pasitọ yii lo lati gbe isọkuṣọ yi lẹsẹ? Iwe mimọ!

Oniwaasu tun le fi idibajẹ sinu aye awọn ọmọ Ọlọrun nipasẹ ala arosọ, iran arosọ, isọtẹlẹ arosọ ati itan arosọ, lati gbin ikoro sinu ọkan wọn lodi si awọn miran, pẹlupẹlu awọn ẹbi wọn. Awọn eniyan si wa loni ti wọn ti kẹyin si awọn ọkọ wọn, aya wọn, obi wọn tabi ọmọ wọn nitoripe awọn oniwaasu kan parọ fun wọn. Ti a ko ba si wa tipasẹ ọrọ Ọlọrun ati agbara Ẹmi Ọlọrun fọ awọn wọnyi mọ, o ṣeeṣe ki ibajẹ ati aiwulo fun Ọlọrun ma fi wọn silẹ fun gbogbo eyi ti o ku lọjọ aye wọn.

Nkan miran ti awọn ayọkẹlẹ bale-ọla-jẹ tun ma n lo lati fi idibajẹ sinu ijọ ni iṣekuṣe. Juuda ni eyi lati sọ fun wa lori ọrọ yi: “Nitori awọn eniyan kan n bẹ ti wọn n yọ wọle, awọn alaiwa-bi-Ọlọrun, ti n yi oore-ọfẹ Ọlọrun wa pada si wọbia, ti wọn si n ṣẹ́ Oluwa wa kanṣoṣo naa, ani Jesu Kirisiti Oluwa.” (Júúdà 4) Njẹ o ri bayẹn? Bi o tilẹ jẹ wipe awọn ayọkẹlẹ bale-ọla-jẹ n pe ara wọn ni Kirisitiẹni, wọn ko jamọ nkankan ju alaiwa-bi-Ọlọrun lọ.

Wayi o, nitoripe awọn eniyan yi ko ni ibẹru Ọlọrun ninu wọn, gbogbo igba ni wọn ma n lo oniruuru arekereke lati tan awọn eniyan Ọlọrun wọnu iṣekuṣe tabi iṣẹ-oṣo. Ibikibi ti iṣedari ijọ kan ko ba si ti wa ni ifura tabi ti igboke-gbodo ko jẹ ki awọn adari ijọ naa gbájúmọ́ ojuṣe wọn, o ṣeeṣe ki aye ati ile ọpọ ti bajẹ tan ki wọn to mọ nkan ti o n ṣẹlẹ.

Siwaju si, awọn ayọkẹlẹ bale-ọla-jẹ ma tun n ṣaba yọkẹlẹ lo ọrọ-ẹyin lati pin awọn eniyan Ọlọrun niya ati lati fi idibajẹ ṣaarin wọn. A ri awọn ijọ loni ti wọn ti n rọju fun ọpọ ọdun lati kuro ni ipo arobo ninu ẹmi, ki wọn si pọ si ni iwulo lọwọ Ọlọrun, ti ko si ti i ṣeeṣe fun wọn. Ki ni idi? Awọn ayọkẹlẹ bale-ọla-jẹ ni ko ma jẹ ki wọn ni isinmi. Gbogbo igba ni wọn n ba ara wọn ja, ti wọn si tun n pari ija laarin ara wọn. Nitorina, wọn ko le gbajumọ igbero ara wọn pẹlu ọrọ Ọlọrun ati idagbasoke wọn ninu oore-ọfẹ Jesu Kirisiti.

Wayi o, ọrọ Ọlọrun ti sọ fun wa ṣiwaju pe idajọ kan ṣoṣo pere lo wa lọwọ Ọlọrun fun awọn ayọkẹlẹ bale-ọla-jẹ. Eyi si ni iparun kiakia. Ranti Kora, Datani, Abiramu ati Oni, awọn ti wọn fẹ fi idibajẹ saarin awọn ọmọ Isiraẹli nipasẹ iṣọte. Nṣe ni a pa ati awọn ati awọn ẹbi wọn run ni kiakia. Tun ranti Ananaya ati Safira, awọn ẹni ti wọn fẹ fi idibajẹ sinu ijọ iṣaaju nipasẹ ififunni pẹlu arekereke. Ni kiakia ni Ọlọrun pa wọn danu. (Wo: Númérì 16; Ìṣe Àpọ́sítélì 5:1-11)

Nitorina, ma ya ayọkẹlẹ bale-ọla-jẹ ninu ijọ Ọlọrun. O ko ni lọ jina rara ti idajọ yoo fi wa sori rẹ. Lafikun, ma ṣe ni nkankan ṣe pẹlu ẹnikẹni ti o ba jẹ ayọkẹlẹ bale-ọla-jẹ ninu ijọ, laarin ẹbi rẹ, ni adugbo rẹ tabi ni ibi-iṣẹ rẹ. Aijẹbẹ, o le pada jẹ alabapin ninu idajọ wọn. Njẹ ki Ẹmi Ọlọrun ṣe ọ ni alailabuku titi ipadabọ Jesu Kirisiti Oluwa wa. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ayọ́kẹ́lẹ́ balé-ọlá-jẹ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 17, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 29 Read More »

Má sọ ààyè rẹ nù

Tẹ̀le tọkàntọk`an | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 10, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 28

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lọpọ-yanturu lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Belu 2024. Adura mi ni pe ki Ọlọrun ma fi ojoojumọ fun ọ ni okun lati ma a tẹle tọkan-tọkan, ki iwọ naa ba a le ma a fi ojoojumọ ni iriri agbara rẹ fun ibalẹ-ọkan ati igbesoke rẹ. Amin.

Lara awọn itan inu bibeli ti o bani-ninujẹ julọ ni itan arakunrin kan ti a n pe ni Gehasi. Tani Gehasi? O jẹ iranṣẹ Wolii Eliṣa, eniyan Ọlọrun nla ni. Ki wa ni o bani-ninujẹ lori itan rẹ? Oun naa ni pe o pari ere-ije rẹ gẹgẹ bi adẹtẹ, bi o tilẹ jẹ wipe oun ni ko ba gba iṣẹ lọwọ Eliṣa gẹgẹ bi i wolii agba ni Isiraẹli.

Bawo wa ni ọkunrin yi ṣe pada di adẹtẹ? Idi kan gbogi ti o fi di adẹtẹ naa ni pe ko fi tọkan-tọkan tẹle eniyan Ọlọrun. Bawo ni a ṣe mọ eyi? Akọkọ, asiko kan wa ti eniyan Ọlọrun yi fun ni ọpa rẹ, ti o si paṣẹ fun pe ki o sare tete lọ fi ọpa yi le ọmọdekunrin kan ti o ku lori, ki ọmọdekunrin naa ba a le pada ji saye. Ara aṣẹ ti a si pa fun tun ni pe ko gbọdọ ki ẹnikẹni loju ọna tabi da ẹnikẹni ti o ba ki i lohun. (Wo: 2Àwọn Ọba 4:29)

Amọ ṣa o, bi a tun ṣe ri ninu akọsilẹ lori rẹ, nṣe ni Gehasi pada de lọjọ yi, ti o si sọ fun eniyan Ọlọrun pe ọmọdekunrin naa ko ji pada saye. Ki lo fa a? Ki lo ṣẹlẹ? A ko sọ fun wa. Ṣugbọn akọsilẹ kan soso ti a ri ninu bibeli ni eyi ninu eyi ti eniyan Ọlọrun yoo ti sọ fun ẹnikan lati lọ ṣe nkan pẹlu agbara Ọlọrun, ti ẹni naa yoo si pada wa lati sọ wipe, “Ko ṣiṣẹ.”

Bi a ti ṣe ri ninu Iwe mimọ, lẹyin igba ti a ti gba Elija soke ọrun, Eliṣa mu agbada rẹ, o si pin odo Jọdani niya pẹlu rẹ, gẹgẹ bi Elija ti ṣe ṣiwaju igbasoke rẹ. Bi o wa tilẹ jẹ wipe Elija ko kọ lati ṣe bẹ ẹ, nipa titẹle tọkan-tọkan, oun naa le gba Ẹmi Ọlọrun kannaa ti o ba Elija ṣiṣẹ lati le ṣe nkan ti o ṣe. (Wo: 2Àwọn Ọba 2)

Siwaju si, a tun ri ninu bibeli pe nigbati Jesu paṣẹ fun awọn ọmọ ẹyin rẹ lati jade lọ ọ waasu ati lati wo oniruuru aisan ati arun san, wọn gbọran si lẹnu. Bi ko tilẹ wa fun wọn ni ọpa tabi owo kankan lati mu lọwọ, gbogbo wọn ni wọn pada pẹlu ẹri ti o ga. Gbogbo wọn ni o le ṣe nkan ti Jesu ti n ṣe. (Wo: Luùkù 10:1-17)

Amọ ọrọ ti Gehasi ma yatọ patapata. Nṣe ni oun pada wa pẹlu iroyin buburu. Nitorina, eniyan Ọlọrun ni lati lọ gbadura fun ọmọdekunrin ti o ku naa funrarẹ, ki o ba a le ye. Mo si tun wa n bere lẹẹkan si, bi mo ti ṣe bere tẹlẹ, “Ki lo ṣele gan-an? Ṣe Gehasi ba ẹnikan sọrọ loju ọna si ọdọ ọmọdekunrin ti o ku yẹn ni? Tabi ṣe o kọkọ ya ibomiran naa ni? Tabi ṣe ko kan tilẹ gbagbọ pe ọmọdekurin naa yoo ye ni?” A ko fun wa ni idahun si awọn ibere wọnyi ninu bibeli. Bẹẹ si ni a ko fi otitọ ti o wa nidi ọrọ naa han eniyan Ọlọrun naa pẹlu ni asiko yi.

Amọ ṣa o, a wa ri asiko kan ti a fi han Eliṣa pe Gehasi ko ma a tẹle tọkan-tọkan. Asiko yi si ni o gbẹyin Eliṣa lọ lati gba owo ati aṣọ diẹ lọwọ Naamani ara Siria. Naamani ni Ọlọrun ti wosan kuro ninu ẹtẹ rẹ. Eliṣa ko si gba ohunkohun lọwọ rẹ nitoripe o fẹ ki o lọ si ile, ki o s jẹ ki awọn eniyan rẹ mọ wipe Ọlọrun kan wa ti O n wo eniyan san lọfẹ. Ṣugbọn Gehasi gbẹ̀bùrú ba ẹri rẹ jẹ nipa gbigba nkan lọwọ rẹ. (Wo: 2Àwọn Ọba 5)

Nitorina, kedere bayi ni o han si eniyan Ọlọrun pe Gehasi ko ma a fi tọkan-tọkan tẹle tabi kọ ẹkọ kankan lara rẹ. Niwọn igba ti ko si tẹle eniyan Ọlọrun yi tọkan-tọkan, a jẹ wipe ko tẹle Ọlọrun tọkan-tọkan naa niyẹn. Eliṣa, bi a ti ṣe mọ ninu bibeli, jẹ eniyan Ọlọrun tootọ. Ki a wa sọ wipe Gehasi n tẹle tọkan-tọkan ni, nṣe ni oun naa ko ba mọ Ọlọrun lotitọ nipasẹ rẹ. Eyi ko ba si jẹ ki o pọ si ni iwulo ninu iṣẹ iranṣẹ. Amọ ọkan rẹ ko mọ. Nitorina, o padanu aaye rẹ ninu ete Ọlọrun, o si tun fa ẹtẹ Naamani si ori ara rẹ ati sori awọn arọmọdọmọ rẹ titi lailai.

Njẹ ki ni eyi n kọ wa? Oun naa ni pe ki a ma a tẹle Ọlọrun tọkan-tọkan. Ọna kan la si ti ṣe bẹ ẹ ni ki a ma a tẹle awọn ti O yan lati dari wa ninu ijọ, ti wọn si n ri ninu ifẹ rẹ lọna ti o han kedere, tọkan-tọkan. Ti awọn adari wa ninu ijọ ko ba n rin ninu ifẹ Ọlọrun, a ko nilo lati tẹle wọn rara. Dipo bẹ ẹ, nṣe ni ki a jina si wọn.

Ṣugbọn ti wọn ba n rin ninu ifẹ rẹ, nṣe ni a ki ma a tẹle wọn tọkan-tọkan. Eyi tunmọ si pe a ko gbọdọ lo oju-aye tabi ẹtan ni titẹle wọn. Dipo eyi, nṣe ni ki a ma a fi gbogbo igba mu ẹkọ wọn, aṣẹ wọn ati adura wọn ni ọkunkundun, ki a si tun ma a ṣiṣẹ le wọn lori. Aijẹbẹ, dipo ti a o fi ma a pada wa sọdọ wọn ni gbogbo igba pẹlu ẹri ti o ga, nṣe ni a o ma fi ọpọ igba mu iroyin ikuna wa tọ wọn wa, gẹgẹ bi Gehasi. Yatọ si iyẹn, a tun le padanu ààyè wa ninu ete Ọlọrun fun wa tabi ki a mu ara wa wa si abẹ idajọ rẹ.

Mo wa gbadura pe o ko ni padanu ààyè rẹ ninu ijọba Ọlọrun tabi di piparun labẹ idajọ rẹ. Ṣugbọn fi ara rẹ jin fun titẹle tọkan-tọkan. Yoo si dara fun ọkan rẹ.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Tẹ̀le tọkàntọk`an | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 10, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 28 Read More »

Ìdí tí o ṣe yẹ kí o máa rìn nínú òdodo | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 03, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 27

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lọpọ yanturu lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu osu Belu, iyẹn oṣu kọkanla ọdun yi. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun kun aye rẹ ninu oṣu naa pẹlu oniruuru ohun rere gbogbo ti yoo jẹ ki o gbagbe inira tabi adanu yowu ti o le ti ni iriri rẹ ninu ọdun yi, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, bi a ti ṣe n bẹrẹ oṣu tuntun naa, mo fẹ gba ọ niyanju lati fi ara rẹ jin siwaju ati siwaju si lati maa ni rin ninu ododo. Ki ni idi? Akọkọ, idi ni pe Ọlọrun ma n tẹ awọn ti o ba n rin ninu ododo lọrun pẹlu ohunkohun ti wọn ba nilo laye, bi o ti wu ki nkan le to nibi ti wọn wọn wa. Jesu sọ wipe, “Alabukun fun ni awọn ti ebi n pa, ti oungbẹ si n gbẹ fun ododo, nitoripe a o tẹ wọn lọrun.” O tun sọ wipe, “Ẹ kọkọ maa wa ijọba Ọlọrun naa, ati ododo rẹ; gbogbo awọn nnkan wọnyi ni a o si fi kun fun yin.” (Wo: Mátíù 5:6 & 6:33)

Nitorinaa, ti o ba fi ara rẹ jin fun ododo, Ọlọrun yoo ri daju pe o ko ṣe alaini ohunkohun ti o dara, bi o ti wu ki nkan buru to nibi ti o ba wa. Lotitọ, iwọ naa gbọdọ kọ bi a ti n tẹwọgba ipese Ọlọrun nipasẹ adura, ijẹwọ ọrọ Ọlọrun ati iṣẹ-afọkanṣe. Amọ o le fọkanbalẹ lori pe Ọlọrun ko ni fi ohunkohun ti o nilo dun ọ, ti o ba fi ara rẹ jin lati ma rin ninu ododo.

Idi keji ti o ṣe yẹ ki o fi ara rẹ jin lati ma rin ninu ododo ni pe Ọlọrun yoo pa ọ mọ bi o ba ti n ṣe bẹ ẹ. Ọkan lara awọn idi ti awọn eniyan ko ki i fẹ fi ara wọn jin fun igbe aye ododo ni ibẹru inunibini. Bi a si ti ṣe ri ninu bibeli, ẹnikẹni ti o ba fẹ gbe igbe aye iwa-bi-Ọlọrun ninu Kirisiti Jesu yoo ba inunibini pade (2Tímótì 3:12). Amọ ṣa o, bibeli tun fi han wa pe aabo wa fun gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun ti o ba fi ara wọn jin fun rinrin ninu ododo kuro lọwọ inunibini. Wọn kan nilo lati kan si Ọlọrun fun un ni.
Fun apẹrẹ, nitori ifarajin Daniẹli fun ododo ni mimojuto iṣẹ rẹ, iyẹn gẹgẹ bi adari ijọba, awọn akẹgbẹ rẹ, ọpọ awọn ẹni ti o jẹ oṣo, ṣe inunibini rẹ gidigan-an. Nigba ti wọn si ri wipe awọn ko le sasi tabi ri aleebu ninu itayọ iṣẹ-iriju rẹ, wọn dẹ pakute fun un. Nitorina, a sọ ọ ninu iho awọn kiniun. (Wo: Dáníẹ́lì 6:1-18)

Njẹ Ọlọrun wa pa a ti bi? Rara o! Dipo bẹ ẹ, nṣe ni O ran angẹli kan lati pa awọn kiniun ti o wa pẹlu rẹ lẹnu mọ. Nitorina, wọn ko le e pa a lara. Nigbẹyingbẹyin, awọn ti o ditẹ mọ ọn, ati awọn aya ati awọn ọmọ wọn, ni o pada di jijẹ fun awọn kininu ti ebi n pa yi i. (Wo: Dáníẹ́lì 6:19-24)

Wayi o, eyi wa ni ibamu pẹlu ọrọ Ọlọrun ti o sọ wipe:

“Nitori yoo fi aṣẹ fun awọn angẹli nipa tirẹ lati pa ọ mọ ni gbogbo ọna rẹ; Wọn yoo gbe ọ soke ni ọwọ wọn, nitori ki iwọ ma ba a fi ẹṣẹ rẹ gun okuta. Iwọ yoo rin lori kinniun ati paramọlẹ, iwọ yoo tẹ kinniun nla ati ejo ni iwọ yoo fi ẹsẹ tẹ mọlẹ. “Nitori ti ifẹ rẹ si mi, Emi yoo gba ọ, emi yoo pa ọ mọ, nitori iwọ jẹwọ orukọ mi.”” (Sáàmù 91:11-14)

Nitorina, ma lailai tun bẹru pe a o ṣe inunibini rẹ mọ nitoripe o n ṣe nkan ti o dara ati ti o tọ niwaju Ọlọrun. Idi si ni pe iwọ yoo ri aabo rẹ gba. Eyi yoo si yọri si igbega rẹ ati si idojuti fun awọn ọta rẹ, gẹgẹ bi o ti ri fun Daniẹli.

Ki o ni oṣu Belu 2024 alarinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ìdí tí o ṣe yẹ kí o máa rìn nínú òdodo | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 03, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 27 Read More »