December 2024

Ayọ̀ rẹ yóò si di kíkún | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀pẹ 29, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 35

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu ayọ ti o ga ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o so ọdun yi, ọdun 2024, pọ mọ ọdun ti a n wo niwaju wa yi, iyẹn ọdun 2025. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ri daju pe o wọ inu ọdun tuntun naa pẹlu akunwọsilẹ ayọ, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, ọkan lara awọn ọna lati ni iriri akunwọsilẹ ayọ lori ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu aye wa ni ki a gbadura. Jesu sọ eyi fun wa nipa ayọ: “Titi di isinyii ẹ ko tii beere ohunkohun ni orukọ mi: ẹ beere, ẹ o si ri gba, ki ayọ yin ki o le kun.” (Jòhánù 16:24) Njẹ o ri bayẹn? Bawo ni a ṣe le ni iriri ayọ ti o kun tabi ẹkunrẹrẹ ayọ ninu aye wa? Nipasẹ gbigbadura si Ọlọrun ni.

Nitorina, ohun ti a nilo lati ṣe ni ki a ṣe idamọ awọn abala aye wa ninu eyi ti inu wa ko ti dun rara tabi ninu eyi ti ayọ wa ko ti kun, ki a si bẹrẹ si ni ba Ọlọrun sọrọ lori wọn. Jesu si ti wa fi da wa loju pe ti a ba ṣe eyi, a o ri idahun si adura wa gba, eyi yoo si yọri si ẹkunrẹrẹ ayọ fun wa. O wa ku si ọwọ wa yala lati gbadura lati ni iriri ẹkunrẹrẹ ayọ ninu aye wa tabi lati ma gbadura, ki a si wa ninu ibanujẹ.

Fun apẹrẹ, bi a ti ṣe sọ fun wa ninu bibeli, Hana fi igbakan ri jẹ onibanujẹ obinrin. Ki ni idi? Akọkọ, idi ni ni pe o ya agan. Ekeji, idi ni pe iyawo ọkọ rẹ keji, iyẹn Pẹnina, ma n pọn loju nitori iyagan rẹ. Lotitọ, ọkọ rẹ, Elikana, ma n saba gbiyanju lati tu u ninu ati lati mu inu rẹ dun. Ṣugbọn idunu ti o n fun ko fi igba kankan to lati ma jẹ ki o sọkun tabi banujẹ mọ.

Amọ ṣa o, ni ọjọ kan, Hana pinnu lati ba Ọlọrun sọrọ lori nkan ti o n fi ojoojumọ ba ninujẹ. Lẹyin asiko adura naa wayi, ibanujẹ poora ninu aye rẹ. Iwọ naa wo diẹ lara nkan ti bibeli sọ lori eyi:“…Bẹẹ ni obinrin naa ba tirẹ lọ, o si jẹun, ko si fa oju ro mọ.” (1Sámúẹ́lì 1:18) Njẹ o ri bayẹn? Nipasẹ adura, ayọ Oluwa gbera dide ninu ọkan Hana, o si le ibanujẹ rẹ lọ. Yatọ si iyẹn, nipasẹ adura rẹ lọjọ yẹn, o ri ọmọdekunrin kan gba lọwọ Oluwa. Eyi si tun wa jẹ ki ayọ rẹ kun akunwọsilẹ.

Nibakanna, ti awa naa ba le gbadura si Ọlọrun lori ohunkohun ti o n yọ wa lẹnu tabi ti o n kun wa pẹlu ibanujẹ, yoo da wa lohun. Lọna wo? Yoo kọkọ jẹ ki ayọ rẹ gbera dide ninu ọkan wa, ki o si le ibanujẹ wa danu. Siwaju si, yoo tun jẹ ki idahun si adura wa ki o farahan. Nipa eyi, ayọ rẹ ti o wa ninu ọkan wa yoo bẹrẹ si kun akunwọsilẹ, yoo si tun yọri si fifi ọpẹ fun un.

Nitorina, bi o tilẹ jẹ wipe a ti wa ni awọn ọjọ ti o kẹyin ọdun yi, mo fẹ ki o mọ wipe ko i ti pẹ ju rara fun ibanujẹ lati di eewọ fun aye rẹ ni gbogbo ọna tabi pẹ ju fun ọ lati ni iriri ẹkunrẹrẹ ayọ lori ohun gbogbo ti o n ni ọ lara. O kan nilo lati gbadura si Ọlọrun ni, bi Hana ti ṣe. Bẹẹni, gbadura si pẹlu ọkan otitọ, ki o si sọ ohun gbogbo ti o n da ọkan rẹ laamu fun un ati ohun ti o fẹ ki O ṣe lori wọn. Yoo si da ọ lohun, yoo le ibanujẹ rẹ danu, yoo si tun ṣe iṣẹ iyanu ti yoo jẹ ki ayọ rẹ kun akunwọsilẹ fun ọ, iyẹn ki ọdun yi to pari.

Wayi o, bi mo ti ṣe n foju sọna fun ẹri rẹ, njẹ ki oore-ọfẹ Jesu Kirisiti Oluwa wa, ifẹ Ọlọrun ati ibadapọ Ẹmi Mimọ jẹ tirẹ lati isinsinyi lọ ati titi lailai. Amin.

A ku imura ọdun o.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ayọ̀ rẹ yóò si di kíkún | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀pẹ 29, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 35 Read More »

Má ba àjọyọ̀ náà jẹ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀pẹ 22, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 34

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lẹkunrẹrẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ kẹrin oṣu Ọpẹ 2024. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun ṣe ayọ rẹ ni akunwọsilẹ ni gbogbo ọjọ yoku ninu ọdun yii. Amin.

Wayi o, bi gbogbo wa ti ṣe mọ, asiko ti a wa yi jẹ eyi ti ọpọ eniyan kaakiri gbogbo agbaye ka si asiko ajọyọ. Bi o si ti wa jẹ pe ko buru ti awa naa ba darapọ ninu ajọyọ naa, a ko gbọdọ gbagbe pe ohunkohun ti a ba n ṣe gẹgẹ bi onigbagbọ ninu Kirisiti Jesu gbọdọ jẹ pẹlu oye ati ni iwọntunwọnsi. Aijẹbẹ, a le ba ajọyọ ara wa jẹ.

Fun apẹrẹ, bi a ti ṣe ri ninu Iwe Mimọ, Dafidi ni asiko kan dari awọn ọmọ Isiraẹli ninu ajọyọ ti o ga lati gbe Apoti Ẹri Oluwa lati ibi ti o wa tẹlẹ lọ si ibi ti o ṣẹṣẹ pese silẹ fun ninu ilu rẹ. O wa ṣeni laanu pe bi ajọyọ naa ti n lọ lọwọ, Ọlọrun lu ẹnikan pa. Bẹẹni, Ọlọrun pa ọdọmọkurin kan ti a n pe ni Usa nitoripe o fi ọwọ kan Apoti Ẹri rẹ nigbati o n gbiyanju lati ma jẹ ki apoti yi re jabọ kuro ninu kẹkẹ ti a gbe sinu rẹ. Eyi si ba ajọyọ ọjọ naa jẹ. (Wo: 2Sámúẹ́lì 6:1-7)

Ki wa ni o jẹ ki Ọlọrun ba ajọyọ awọn eniyan rẹ jẹ lọna yi? Ti o ba jẹ wipe Satani ni o ba ajọyọ wọn jẹ, ko ni jẹ kayefi. Ṣugbọn ko ki i ṣe Satani ni o ba ajọyọ wọn jẹ — Ọlọrun ni o ba a jẹ. Si wa wo o, Oun naa ni wọn n yin lọjọ ti a n wi yi o. Ki wa lo fa ti O fi ba ajọyọ wọn jẹ?

Ni kukuru, gẹgẹ bi Dafidi ti sọ lẹyin-ọ-rẹyin, nitoripe wọn ko tẹle ilana Ọlọrun ni mimojuto Apoti Ẹri rẹ ni O ṣe ba ajọyọ wọn jẹ. O wa jasi pe aimọkan-mọkan wọn ni o fi aye silẹ fun idajọ Ọlọrun ti o sọ ọjọ ajọyọ di ọjọ ẹkun fun gbogbo orilẹ-ede wọn lati wa sori wọn. Eyi si n kọ wa pe aimọkan-mọkan le ba ajọyọ jẹ. Nitorina, bi o ti ṣe n yọ lori didara Ọlọrun ni asiko yi, ma gbagbe ara rẹ debi wipe o o bẹrẹ si ni tọwọbọ awọn nkan ti o ko ni oye nipa wọn tabi awọn nkan ti o ga ju ọ lọ. Aijẹbẹ, idajọ Ọlọrun tabi ikọlu Satani le run ajọyọ rẹ.

Siwaju si, bi mo ti ṣe sọ tẹlẹ, ajọyọ wa ni asiko yi gbọdọ jẹ iwọntunwọnsi. Jẹun ni iwọntunwọnsi. Mu ni iwọntunwọnsi. Wọṣọ ni iwọntunwọnsi. Si tun na owo ni iwọntunwọnsi. Ma sọ ara rẹ di alajẹnu nitoripe asiko ajọyọ ni o wa. Ma si ko sinu gbese tabi ki o fi iwa omugo naa owo rẹ nitori ajọyọ. Aijẹbẹ, o le ba orukọ ara rẹ jẹ.

Bibeli sọ eyi fun gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun: “Ẹ maa ṣe ohun gbogbo bi o ti tọ ati bi o ti yẹ.” (1Kọ́ríntì 14:40) Lotitọ, lori awọn ipade wa gan ni a mọ-ọn-mọ sọ ọrọ yi le. Amọ o tun ṣe e lo pẹlu fun bi a ti ṣe n mojuto aye wa. A gbọdọ ṣe ohun gbogbo ni iwọntunwọnsi ati lẹsẹẹsẹ. Nitorina, bi a ti ṣe n yọ lori didara Ọlọrun, a gbọdọ ṣe e pẹlu ọgbọn. Aijẹbẹ, a le si ilẹkun aye wa silẹ fun awọn ijamba, ewu tabi abamọ ti o ṣe e yago fun, ki a si ba ajọwọ wa jẹ. Mo gbadura wipe ọdun yi ko ni pari pẹlu abamọ ati ibanujẹ fun ọ tabi fun ile rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

A ku imura ọdun Keresi o

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Má ba àjọyọ̀ náà jẹ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀pẹ 22, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 34 Read More »

Kí Sàtánì má bá à rí ọ lò | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀pẹ 15, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 33

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ọ̀pẹ 2024. Adura mi si ni pe Satani ko ni ṣe aṣeyọri rara lati ri ọ lo lati ṣe ara rẹ tabi awọn miran ni ijamba ni gbogbo eyi ti o ku ninu ọdun yi. Amin.

Ọkan lara awọn aṣẹ ti a pa fun wa ninu Iwe Mimọ ni pe ki a ma ṣe fun eṣu laaye (Éfésù 4:27). Eyi jasi pe a ko gbọdọ fun ni anfaani lati ṣiṣẹ ninu aye wa tabi lati lo wa lati ṣiṣẹ ninu aye awọn miran. Ṣugbọn ti a ko ba ti ilẹkun ọkan wa mọ ohun gbogbo ti o n jẹ ibi, Satani le ṣe aṣeyọri lati ri wa lo lati pa ara wa tabi awọn miran lara kọja ero ọkan wa.

Fun apẹẹrẹ, nitoripe Judasi Isikariọti ko ti ilẹkun ọkan rẹ mọ ojukokoro, Satani ṣe aṣeyọri lati mu un lẹru ati lati lo lati ṣẹ́ Jesu Kirisiti Oluwa wa. Nigbati iye rẹ si wa sọ pada, ti o ri wipe Satani ti ya ohun lo, ara rẹ ko gba itiju ti o tẹle. Nitorina, lẹkaansi, Satani kun ọkan rẹ pẹlu abamọ ati ibanujẹ to bẹẹ ti o fi lọ pokunso. Ti awa naa ko ba wa gbe ilẹkun ọkan wa ti mọ ojukokoro, Satani le ṣe aṣeyọri ni lilo wa lati pa awọn ti a fẹran run ati ara wa pẹlu. (Wo: Mátíù 27:3-5; Jòhánù 13:2&27)

Ọba Sọọlu nkọ? Nitoripe o kọ lati ti ilẹkun ọkan rẹ mọ ẹtanu ati owu jijẹ, Satani mu un lẹru, o si sọ ọ di apaniyan. O wa pa ojuṣe rẹ gẹgẹ bi ọba ti, o si bẹrẹ si ni le Dafidi, ọdọmọkurin alaiṣẹ ti ko ṣe ni ibi, kaakiri, lati ibikan si ibomiran, lati mu un ati lati pa a. Ko si wa dẹkun lati ma fi aye rẹ ṣofo lọna yi titi o fi ku.

Nibakana, ti a ba fi aye gba owu tabi ẹtanu ninu ọkan wa, Satani le mu wa lẹru, ki o si bẹrẹ si ni lo wa lati lepa iparun awọn alaiṣẹ, dipo ti a o fi ma lepa imuṣẹ awọn eto Ọlọrun fun aye wa. Nibi ti eyi ba si ti ri bẹ ẹ, o di dandan ki a fi aye wa ṣofo.

Lafikun, nipasẹ igberaga, Satani le mu ọkan wa lẹru, ki o si bẹrẹ si ni lo wọn lati ṣe awọn nkan ti a o pada kabamọ, awọn nkan ti yoo fi wa si abẹ idajọ Ọlọrun. Fun apẹrẹ, nitori igberaga Dafidi, nitoripe o fẹ ma fi bi awọn ọmọ Isiraẹli ṣe pọ to yangan, Satani ṣe aṣeyọri ni lilo o lati ṣe ikaniyan wọn. Nipa ṣiṣe eyi, o fi ara rẹ ati awọn eniyan naa si abẹ idajọ Ọlọrun. Ti ko ba wa jẹ wipe Ọlọrun ṣaanu fun ilẹ naa ni, boya eniyan perete ni a ko ba fi silẹ láàyè. (Wo: 1Kíróníkà 21)

Ṣe o wa ri bayi pe bi a tilẹ fẹran Ọlọrun gidigidi bi Dafidi, ti a ba fi aye gba igberaga ninu ọkan wa, Satani le ya wa lo. Ta wa ni o mọ irufẹ ipalara ti o le ṣe nipasẹ wa? Nitorina, bi a ti wọ inu awọn ọjọ ti o gbẹyin ọdun yi, ri daju pe o fi aye gba ọrọ Ọlọrun lati ya ọ ya ohun gbogbo ti o n jẹ ero ibi, paapaa julọ, igberaga, etanu, owu, ojukokoro, ainitẹlọrun ati ifẹkufẹ. Nipa ṣiṣe eyi, Satani ko ni le e ri ọ lo lati ba ayọ ati ibalẹ-ọkan ara rẹ jẹ tabi lati pa awọn miran run. Njẹ ki Ẹmi Ọlọrun fun ọ ni okun lati ṣe bẹẹ gẹgẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Kí Sàtánì má bá à rí ọ lò | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀pẹ 15, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 33 Read More »

Jẹ́ kí ọkàn rẹ dìrọ̀ mọ́-ọn pátápátá | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀pẹ 08, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 32

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu ayọ ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ keji ninu oṣu Ọ̀pẹ 2024. Mo si gbadura pe ki ọkan rẹ ma fi igba gbogbo gba okun lati má kọ Ọlọrun alaaye silẹ fun ọlọrunkọlọrun miran, bi o ti wu ki idojukọ rẹ le e to laye yi, ki o ba a le ma fi ojoojumọ ri ifarahan iyanu agbara rẹ fun ire rẹ. Amin.

Bibeli sọ pe, “Nitori ti oju Oluwa n lọ siwa, sẹyin ni gbogbo aye, lati fi agbara fun awọn ti ọkan wọn wa ni pipe si ọdọ rẹ…” (2Kíróníkà 16:9) Njẹ o ri bayi? Gbogbo igba ni Ọlọrun n foju wa awọn ti O le fi agbara rẹ han fun wọn. Ki si ni yoo jẹ ki O fi agbara rẹ han fun igbala, aabo tabi igbega wọn? Fifi gbogbo ọkan wọn jin fun jin fun ni yoo jẹ ki O ṣe bẹ ẹ.

Wo o, ti o ba fi gbogbo ọkan rẹ jin fun Ọlọrun, wa mu ọrọ rẹ, adura gbigba ati ibadapọ pẹlu awọn ara ninu ijọ ni ọkunkundun. Lafikun, ti o ba fi gbogbo ọkan rẹ jin fun Ọlọrun, o ko ni lailai yi pada kuro lọdọ rẹ si ọdọ ọlọrun miran fun iranwọ. O wa ṣeni laanu pe ọpọ ninu ijọ loni ni o ti yipada kuro lọdọ Ọlọrun si idi iṣẹ oṣo lati di olowo, lati gba iwosan fun ailera wọn tabi lati gba itusilẹ kuro lọwọ iyagan wọn.

Wayi O, irufẹ awọn eniyan wọnyi ko le ni iriri agbara Ọlọrun fun ire wọn bi o ti ṣe tọ. Dipo eyi, ti wọn ba lọra lati ronupiwada, idajọ Ọlọrun le wa sori wọn, ki O si pa ati awọn ati awọn nkan ti wọn gba lọwọ oṣu tabi ti wọn n gbiyanju lati daabo bo run. Bi a ti ṣe ri ninu bible, idi pataki ti Ọba Ahasaya ṣe ku lati ipasẹ ọgbẹ ti o ni nigba ti o ṣubu ninu aafin rẹ ko ju pe o tọ ọlọrun miran lọ fun iwosan dipo Ọlọrun alaaye. Lafikun, ọkan gbogi lara idi ti Ọba Asa ṣe ku ṣaaju asiko rẹ ni pe o kọ lati tọ Ọlọrun lọ fun iwosan rẹ — awọn oniṣegun rẹ nikan ti o n tọ lọ. (Wo: 2Àwọn Ọba 1; 2Kíróníkà 16)

Ṣe o wa ri bayi pe awọn ti ko fi ọkan wọn jin patapata fun Ọlọrun fun ohunkohun ti wọn ba nilo ṣeeṣe ki wọn padanu lọna meji. Akọkọ, wọn yoo padanu ifarahan agbara rẹ fun wọn. Ekeji, wọn yoo padanu ohun yowu ti wọn n gbiyanju lati pa mọ tabi daabo bo lalai fi ti iranwọ rẹ ṣe.

Nitorina, ti a ba ri ọna kan tabi omiran ti o ko ti fi ọkan rẹ jin patapata fun Ọlọrun, ti a ba ri abala aye rẹ kan ninu eyi ti o ti n wa iranlọwọ fun ara rẹ lọdọ awọn miran yatọ si Ọlọrun, nṣe ni ki o yara tete ronupiwada. Aijẹbẹ, nigba ti awọn ọmọ Ọlọrun yoku ba n ni ẹri giga didara rẹ lati jẹ, o ṣeeṣe ki o jẹ wipe nṣe ni wa ma a yíràá ninu inira ati idojuti. Adura mi ni pe eyi ko ni jẹ ipin rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Jẹ́ kí ọkàn rẹ dìrọ̀ mọ́-ọn pátápátá | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀pẹ 08, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 32 Read More »