January 2025

Kí ọjọ́ ibi tó dé | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Sẹrẹ 26, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 39

Olufẹ: Ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o pari oṣu Sẹrẹ. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun ma fi ojoojumọ fun ọ ni iwuri lati ma ṣe amulo ti o peye oore-ọfẹ rẹ lati jẹ alagbara ninu rẹ, ki ọjọ ibi kankan ma ba bori rẹ. Amin.

Ninu lẹta rẹ si awọn ara Efesu, Pọọlu sọ wipe, “Nitori naa, ẹ gbe gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ, ki ẹyin le duro tiiri si ọjọ ibi, nigba ti ẹyin ba si ti ṣe ohun gbogbo tan ki ẹ si duro.” (Éfésù 6:13) Ki ni aṣẹ si awọn eniyan Ọlọrun nibiyi? Oun naa ni pe ki wọn gbe gbogbo imọra Ọlọrun wọ. Eyi jasi pe ki wọn ṣe amulo ohun yowu ti Ọlọrun ti pese fun aabo wọn lati da aabo bo ara wọn. Nitorina, eyi ko ki i ṣe nkan ti Ọlọrun yoo ṣe fun wọn; dipo bẹẹ, o jẹ nkan ti wọn yoo ṣe fun ara wọn.

Wayi o, ki ni idi ti o ṣe ṣe pataki ki awọn eniyan Ọlọrun ṣe eyi? Oun naa ni ki wọn ba a le duro ṣinṣin nigba ti ọjọ ibi ba de. Nitorina, daju-ṣaka ni pe awọn ọjọ ibi kan yoo tọ ọmọ Ọlọrun kọọkan wa. Lotitọ, ko si ọjọ kan ti ko ni ibi ninu rẹ, o kere tabi o pọ. Ṣugbọn awọn ọjọ kan a ma a wa ninu eyi ti o jẹ wipe a n taari awọn ibi kan si ọkọọkan ninu wa. Nitori irufẹ awọn ọjọ wọnyi gan ni a ṣe nilo lati wa ni aabo pẹlu ihamọra Ọlọrun.

Fun apẹrẹ, asiko kan wa ti awọn kan kora wọn jọ papọ lati gbogun ti Daniẹli lati parun. Lọna wo? Nipa titan Ọba Darusi jẹ lati pasẹ pe ki gbogbo awọn ti o wa ninu ijọba rẹ ma ṣe gbadura si ọlọrun-kọlọrun kankan ayafi oun. Bi aṣe naa si ṣe sọ, aigbọran si i yoo sọ ẹni ti ọrọ ba kan di ero inu iho kiniun. (Wo: Dáníẹ́lì 6:1-9)

Ki wa lo fa ti awọn ọkunrin yi ṣe gbe irufẹ igbese yi? Idi ni pe wọn mọ pe idi ti awọn ko ṣe ri Daniẹli parun ṣaaju asiko naa ni pe o jẹ aladura ati ẹnikan ti o bẹru Ọlọrun. Nitorina, ero wọn ni pe ti awọn ba le di lọwọ lati ma gbadura fun o kere ju oṣu kan, o yẹ ki ọwọ awọn le tẹ ẹ, ki awọn si ri parun. Ti o ba si wa tẹsiwaju lati ma a gbadura, lodi si aṣẹ ọba, a jẹ wipe inu iho awọn kininu ni yoo ti ba ara rẹ niyẹn. Nitorina, ni ti wọn o, ko si ọna abayọ rara fun ọkunrin naa.

Amọ wọn kuna. Wọn kuna nitoripe Daniẹli ko lailai dẹkun lati ma a gbadura si Ọlọrun, bi o tilẹ jẹ wipe eyi tako aṣẹ ọba. Dipo bẹẹ, nṣe ni o tẹsiwaju lati ma a gbadura ati lati ma a gbadura lọna ti awọn ọta rẹ gan yoo fi mọ wipe o n gbadura. Ṣugbọn ọjọ ibi ni asiko yi jẹ fun un. Ọjọ ti gbogbo awọn ika ijoye Ọba Darusi gbogun ti ni. Ọjọ ti ọba funrarẹ gan ko le ran an lọwọ tabi gbala ni o jẹ. (Wo: Dáníẹ́lì 6:10)

Ki lo wa fa ti o fi tẹsiwaju lati ma a gbadura si Ọlọrun? O tẹsiwaju lati ma a gbadura si i nitoripe o ti ri daju-daju pe Ọlọrun ni ohun gbogbo fun oun. Ọkunrin yi ti n ṣe aṣaro lori ọrọ Ọlọrun, ti o si tun gbadura fun ọpọ ọdun saaju asiko yi. Eyi si ti gbe igbagbọ rẹ ro debi wipe ko si ihalẹ ẹnikẹni ti o le mi i. Nitorina, bi o tilẹ jẹ wipe gbogbo eniyan gbogun ti lasiko naa, ko tilẹ mira rara. Idi si ni pe o mọ wipe Ọlọrun le pa oun mọ.

Ṣe Ọlọrun wa pa a mọ tabi ko pa a mọ? Ọlọrun ma pa a mọ, O si tun dojuti gbogbo awọn ọta rẹ. Ṣugbọn ka wa sọ wipe ko ma gbe igbagbọ rẹ ro ki ọjọ ibi yi to de nkọ? Njẹ ko ni di ẹni iparun bi? Yoo fẹrẹ di ẹni iparun.

Ki gan wa ni koko nkan ti a n sọ? Oun naa ni pe ko yẹ ki a duro de ọjọ ibi ki a to bẹrẹ si ni gbe igbagbọ wa ninu Ọlọrun ro tabi ki a to bẹrẹ si ni wa aabo rẹ. Ki a tilẹ sọ otitọ, a le e ma ranti tabi ki a ma ni igboya to lati wa aabo Ọlọrun nigba ti ọjọ ibi ba de, ti ko ba ti mọ wa lara tẹlẹ lati ma fa aye wa le e lọwọ.

Iwọ naa ro eyi wo: Njẹ eni ti ko ni gbadura nigba ti ko si ofin ti o lodi si adura gbigba yoo gbadura bi, ti ofin ba a le wa ti o lodi si i? Ko fẹrẹ jọ bẹẹ! Nitorina, ko ni fẹ ṣeeṣe ki o fi igbagbọ ninu Ọlọrun han lọjọ ibi, igbagbọ ti o ko ni ninu rẹ ni asiko ti nkan rọrun fun ọ. Idi niyi ti o fi jẹ pe nisinsinyi gan an ni o yẹ ki o gbe gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ. Aijẹbẹ, o ko ni ni idahun fun eṣu nigba ti ojọ ibi ba de.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Kí ọjọ́ ibi tó dé | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Sẹrẹ 26, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 39 Read More »

Kìkì àwọn péréte | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Sẹrẹ 19, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 38

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Sẹrẹ 2025. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun sọ ọ ji lati ṣe idamọ gbogbo ojuṣe iṣẹ iranṣẹ rẹ, ki O si tun fun ọ ni okun lati bẹrẹ si ni ṣe wọn lalai dẹsẹ duro. Amin.

Pọọlu, ninu lẹta rẹ kan si Timoti, sọ eyi fun un: “…Ṣe iṣẹ rẹ laṣepe.” (2Tímótì 4:5) Ki ni idi ti o ṣe sọ eyi fun un? O sọ eyi fun un nitoripe o mọ daju pe o mọ iṣẹ iranṣẹ rẹ ati awọn ojuṣe ti o soro mọ-ọn. Ti Timoti ko ba mọ ojuṣe iṣẹ iranṣẹ, ko si bi yoo ṣe le mọ-ọn-mọ mu wọn ṣẹ. Lotitọ, o le ṣeesi ṣe diẹ lara ojuṣe iṣẹ iranṣẹ rẹ, bi ko tilẹ mọ wọn. Ṣugbọn ko si bi o ṣe le mọ-ọn-ọn ṣe awọn ojuṣe ti ko mọ rara gẹgẹ bi ojuṣe rẹ laṣepe.

Wayi o, ti Timoti ko ba wa ma a ṣe awọn ojuṣe iṣẹ iranṣẹ rẹ laṣepe, Ọlọrun ko ni i le bukun fun ẹnikọọkan ti O fẹ tipasẹ iṣẹ iranṣẹ rẹ bukun fun bi O ti ṣe fẹ. Ṣe inu Ọlọrun yoo si dun si eyi bi? Rara, inu rẹ ko ni dun si. Nitorina, nṣe ni yoo nilo lati wa awọn ọna ti yoo gba sọ ọ ji lati ṣe gbogbo nkan ti o yẹ ki o ṣe tabi ki O wa awọn miran ti wọn yoo ṣe ohun ti o yẹ ki o ṣe ṣugbọn ti o n pati.

Nibakanna, Ọlọrun n reti ki ọmọ rẹ kọọkan ninu ijọ loni ṣe idamọ awọn ojuṣe iṣẹ iransẹ rẹ, ki o si bẹrẹ si ni ṣe wọn. Aijẹbẹ, ko ni le bukun fun awọn ti O fẹ tipasẹ rẹ bukun fun. Ibi ti eyi ba si ti ribẹ, yoo nilo lati wa ọna lati sọ wọn ji lati ṣe awọn iṣẹ ti wọn n pa a ti tabi lati wa awọn miran ti wọn yoo ṣe e.

O wa ṣeni laanu pe bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun n ṣe ohun gbogbo ti O le ṣe lati sọ ọpọ wa ji si awọn nkan ti o jẹ ojuṣe iṣẹ iransẹ wa, ọpọ igba ni a ko ki i ṣetan lati sọji nitori ibẹru, imẹlẹ, ailepa-ọkan-pọ, ojukokoro tabi aimọkanmọkan. Nitorina, ọpọ igba, ni Oun naa ma n nilo lati pe awọn miran lati ṣe awọn nkan ti a n kọ lati ṣe. Idi si niyi ti o fi jẹ wipe, ni ọpọ awọn ijọ Kirisitiẹni, awọn perete ti o fi ara wọn jin fun ọrọ Ọlọrun naa ni o tun ma n ṣaba fi ara wọn jin fun adura gbigba, ibẹwo, ififunni ati mimojuto awọn ile ijọsin wọn.

Fun apẹrẹ, ninu lẹta rẹ kan si awọn ara Kọrinti, o sọ eyi fun wọn: “Mo layọ fun wiwa Sitefana ati Foritunatu ati Akayaku: nitori eyi ti o ku nipa ti yin wọn ti fi kun un.” (1Kọ́ríntì 16:17) Njẹ o ri bayẹn? Daju-ṣaka ni pe alagba ijọ Kọrinti ni awọn ọkunrin mẹta wọnyi. Eyi jasi pe wọn gbọdọ ni ọpọlọpọ ojuṣe ti wọn n gbe ni asiko naa. Sibẹsibẹ, bi ijọ Kọrinti yoo ti tobi to ni asiko yẹn, awọn ọkunrin mẹta yi i naa ni o tun fi nkan ini wọn ran Pọọlu lọwọ lati mojuto nkan ti gbogbo ijọ wọn yẹ ki o ṣe.

Njẹ eyi wa jẹ nkan ti o dara lati ma ṣẹlẹ ninu ijọ Ọlọrun kankan? Rara o! Ṣe awọn perete ni o yẹ ki wọn ma gbe gbogbo ẹru ti o yẹ ki gbogbo awọn ọmọ ijọ wọn ma a gbe? Rara o! Ṣe ko tilẹ ṣeeṣe ki o rẹ awọn perete wọnyi tabi ki irẹwẹsi mu wọn ni asiko kan, ki wọn si ma fẹ ṣe nkankan mọ? O ṣeeṣe. A si ti ri awọn eniyan ti irẹwẹsi mu, ti wọn si dẹkun lati ma lọ si awọn ipade ijọ wọn patapata nitoripe ẹru ti wọn n gbe wọ wọn lọrun.

Siwaju si, bi irẹwẹsi ko tilẹ mu awọn wọnyi, ṣe ko ki i ṣe awọn nikan ni Ọlọrun yoo pin ni ere ti o ye ki o jẹ ti gbogbo ijọ wọn? Awọn nikan naa ni yoo pin ni ere yi. Idi si ni pe Ọlọrun ko ni lailai pin eniyan lere fun ohun ti ẹni naa ko ba ṣe fun un. Yatọ si iyẹn, idagbasoke ati ilọsiwaju ijọ ninu eyi ti o jẹ wipe awọn perete nikan ni o ṣe ohun gbogbo ti o yẹ ki o jẹ ṣiṣe yoo lọra. Eyi yoo si jẹ ki o ri idi ti a fi ni ọpọlọpọ ijọ ni ilẹ wa ti wọn ti wa fun ọpọ ọdun ṣugbọn ti wọn si tun jẹ èwe ninu isesorere ati iwulo.

Ni kukukru, mo n sọ awọn nkan wọnyi fun ọ lati jẹ ki o mọ wipe ko ki i ṣe nkan ti o dara ni fun wa gẹgẹ bi ijọ lati fi awọn nkan ti o yẹ ki gbogbo wa ma a ṣe fun Ọlọrun silẹ fun awọn kiki awọn melokan lati ṣe. Ti eyi ba si ri bẹ, a jẹ wipe a ti n ṣeesi di idagbsoke ati iwulo ijọ wa lọwọ niyẹn ati wipe o ṣeeṣe ki a tilẹ ti ma fi irẹwẹsi kun ọkan awọn kọọkan larin wa. Nitorina, a nilo lati ronupiwada, ki a si bẹrẹ gbe ojuṣe wa ninu adura gbigba, ififunni, ibẹniwo ati bẹẹbẹẹ lọ. Nigba naa ni ijọ waa yoo bẹrẹ si ni dagbasoke ati pọ si ni iwulo bi o ti ṣe tọ, nigba naa si tun awa naa ko ni padanu ere wa si ọwọ awọn miran.

Ki o ni ọsẹ atata.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Kìkì àwọn péréte | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Sẹrẹ 19, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 38 Read More »

Tí o bá fẹ́ èrè tí ó suwọ̀n ju tàtẹ̀yìnwá lọ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Sẹrẹ 12, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 37

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu idunnu ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Sẹrẹ 2025. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun dari rẹ nipasẹ Ẹmi rẹ lati gbe gbogbo igbesẹ ti o tọ fun ọ lati tayọ ni gbogbo ọna rẹ ninu ọdun naa, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, ni ibẹrẹ ọdun bi eyi, nkan ti o wopọ ni ki awọn eniyan ma pongbẹ lati gbe igbe aye ti o suwọn si ati lati ri ere ti o suwọn ju ti atẹyinwa lọ lori awọn akitiyan wọn. Ko si si nkan ti o buru ninu eyi. Amọ ṣa o, pe a n pongbẹ lati gbe igbe aye ti o suwọn si ko to fun wa lati gbe igbe aye ti o suwọn si. Nibakanna, pe a n pongbẹ lati ri ere ti o suwọn ju tatẹyinwa lọ laye ko to fun wa lati ri ere ti o suwọn ju tatẹyinwa lọ. Ti a ko ba ma a ṣe awọn nkan ti yoo jẹ ki a gbe igbe aye ti o suwọn si ati ti yoo jẹ ki a ri ere ti o suwọn ju tatẹyinwa lọ lori awọn akitiyan wa lọna ti o peye, a ko ni gbe igbe aye ti o suwọn si tabi ri ere ti o suwọn si.

Bibeli sọ wipe, “Ki a ma ṣe tan yin jẹ; a ko le gan Ọlọrun: nitori ohunkohun ti eniyan ba funrugbin, ohun ni yoo si ka.” (Gàlátíà 6:7) Ki ni eyi tunmọ si? Nkan ti o tunmọ si ni pe Ọlọrun ti fi ofin kan kalẹ ti o sọ wipe ohun ti eniyan ba gbin laye yi ni yoo ka. Nitorina, lakọkọ, o ko le kore ohun ti o ko ba gbin. Ekeji, o ko le yi ikore ohun ti o ba ti gbin pada – ohun ti o ba gbin naa ni o o ka.

Nitorina, ti o ba fẹ gbe igbe aye ti o suwọn si, ti o si tun fẹ je ere ti o suwọn si lori awọn akitiyan rẹ lọdun yi, ibere akọkọ ti o gbọdọ bere lọwọ ara rẹ ni pe, “Njẹ mo n gbin ohunkohun rara ti o le jẹ ki n gbe igbe aye ti o suwọn si ati ti o le jẹ ki n jere ti o suwọn ju tatẹyinwa lọ?” Ti o ko ba gbin nkankan sinu aye yi, ko yẹ ki o reti ikore kankan lori ohun ti o ko gbin. Kiki awọn ti o ba n gbin nkan ni o ni anfaani lati ma foju sọna fun ikore nkan ti wọn n gbin.

Ibere keji ti o nilo lati bere lọwọ ara rẹ ni pe, “Irufẹ irugbin wo ni mo n gbin?” Bi mo ti ṣe sọ siwaju, o ko le yi ikore irugbin yowu ti o ba ti gbin pada. Nkan ti o ba gbin naa ni iwọ yoo ka. Nitorina, ti o ba fẹ igbe aye ti o suwọn ju tatẹyinwa lọ, ti o si tun fe ere ti o suwọn ju tatẹyinwa lọ lọdun yi, o ṣeeṣe ki o nilo lati parọ irugbin ti o n fun. Fun apẹrẹ, ti o ba jẹ pe irugbin ti ibẹru, imẹlẹ, anikanjọpọn, ẹtanu, ikunsinu tabi ọrọ buburu ti fi idibajẹ si ni o n fun, o gbọdọ parọ rẹ si irugbọin igbagbọ, ifẹ, iṣẹ-aṣekara, iṣoore, adura gbigba ati ọrọ Ọlọrun. Aijẹbẹ, ko si bi o ti ṣe tiraka to lọdun yi, o ko le gbe igbe aye ti o suwọn si tabi jẹ ere ti o suwọn ju tatẹyinwa lọ. Dipo bẹẹ, o ṣeese ki nkan tun wa buru si fun ọ.

Siwaju si, bi o tilẹ wa jẹ wipe irugbin igbagbọ, ifẹ, iṣẹ-aṣekara, iṣoore, adura gbigba ati ọrọ Ọlọrun ni o n fun, o tun nilo lati fun ọpọlọpọ awọn irugbin yi si, ki o ba a le ni ikore wọn lọna ti o pọ si lati ara igbe aye ti suwọn si ati ere ti o suwọn si. Ranti pe nkan ti o ba gbin naa ni o o ka. Lotitọ, Ọlọrun le fun ọ ni ikore irugbin ti o gbin ni ilọpo-ilọpo lọna ti o ga. Amọ ṣa o, nkan ti o ba gbin nikan naa ni O le sọ di ilọpo fun ọ, ko si ṣe eyi ti o ko ba gbin. Nitorina, ti o ba jẹ ọgọrun irugbin ni o fun, ọgọrun irugbin yi naa ni yoo sọ di ilọpo-ilọpo fun ọ. Ti o ba si jẹ ẹgbẹrun irugbin ni o fun, ẹgbẹrun kan yi naa ni yoo sọ di ilọpo-ilọpo fun ọ. Ko si ojuṣaaju pẹlu rẹ.

Nitorina, ti o ba n fẹ lati ni iriri iṣorire ati ijẹgbadun ti o suwọn ju tatẹyinwa lọ ninu ọdun yi, ṣetan lati fun irugbin rere ti o pọ ju tatẹyinwa lọ. Bi o si ti ṣe n ṣe eyi, mo gbadura pe ki Ọlọrun sọ ere ilakaka rẹ di ilọpo-ilọpo fun ọ, ki O si tun fun ọ ni isinmi ni gbogbo ayika rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Tí o bá fẹ́ èrè tí ó suwọ̀n ju tàtẹ̀yìnwá lọ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Sẹrẹ 12, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 37 Read More »

Àdúrà mi fún ọ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Sẹrẹ 05, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 36

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lẹkunrẹrẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ si ọjọ Isinmi akọkọ ninu ọdun tuntun yi, ọdun 2025. Daju ṣaka ni pe nitori didara Oluwa si wa ni a ṣe wa laaye ati ni alaafia lati ri ọdun tuntun naa. Nitorina, mo fẹ ki o darapọ mọ mi lati kọ orin yi ti o sọ pe:

O ṣeun, Oluwa
O ṣeun, Oluwa
Gbogbo nkan ti mo le sọ naa ko ju pe ‘O ṣeun, Oluwa’.

Wayi o, bi a ti ṣe n bẹrẹ ọdun yi, mo fẹ gba fun iwọ naa adura Apọsiteli Johanu fun ọrẹ rẹ kan, ti o ka bayi: “Olufẹ, emi n gbadura pe ki o le ma a jẹgbadun ilera ti o peye, ki o si maa dara fun ọ ninu ohun gbogbo, ani bi o ti dara fun ọkan rẹ.” (3Jòhánù 3) Ki ni nkan akọkọ ti Johanu n tọrọ lọwọ Ọlọrun lati ṣe fun ọrẹ rẹ? Ohun naa ni pe ki O jẹ ki o ma a jẹgbadun ilera ti o peye.

Ki ni idi ti eyi ṣe ṣe pataki? O ṣe pataki nitoripe lalai si ilera ti o peye, yoo nira, iyẹn ti o ba tilẹ ṣeeṣe, fun ẹnikẹni lati ṣe nkankan ti o nitumọ fun Ọlọrun, fun ara rẹ tabi fun awọn miran. Lafikun, lalai si ilera ti o peye, awọn eniyan ko le gbadun aye wọn tabi ohunkohun ti wọn ni. Emi si wa fẹ ki o le gbe oniruuru nkan ti o nitumọ ṣe fun Ọlọrun, fun ara rẹ ati fun awọn miran lọdun yi. Mo tun fẹ ki o le jẹgbadun aye rẹ, awọn ibaṣepọ rẹ ati ohun rere yowu ti Ọlọrun ba ṣe fun ọ tabi fi fun ọ ninu ọdun naa. Nitorina, gẹgẹ bi Johanu ti ṣe gbadura fun ilera ti o peye fun ọrẹ rẹ, emi naa tun n gba ladura fun iwọ naa pe ki o jẹdadun ilera ti o peye ni gbogbo ọdun tuntun yi, ki o ba a le ni okun to lati ṣe ohun rere yowu ti ọkan rẹ ba n fẹ lati ṣe ati ki o ba a le jẹgbadun aye rẹ ati ohun gbogbo ti o ni. Amin.

Ki ni nkan keji ti Johanu n tọrọ lọwọ Ọlọrun fun ọrẹ rẹ? Oun naa ni pe ki o le maa dara fun ninu ohun gbogbo. Njẹ iwọ naa ko ha fẹ ki o dara fun ọ ninu ohun gbogbo ninu ọdun yi bi? Njẹ o ko ha fẹ ki o dara fun ẹbi rẹ, okowo rẹ, ẹkọ rẹ, iṣẹ-iranṣẹ rẹ ati ohun yowu ti o ni i ṣe pẹlu aye rẹ bi ninu ọdun yi? Emi n fẹ ki o dara fun mi ninu ohun gbogbo lọdun yi. Adura mi naa si wa ni pe ki o dara fun iwọ naa ninu ohun gbogbo ni ojoojumọ ọdun tuntun yi. Amin.

Nkan ẹkẹta ti Johanu bere lọwọ Ọlọrun fun ọrẹ rẹ ni pe ki o ma a dara fun ọkan rẹ ninu ibaṣepọ rẹ pẹlu Ọlọrun. Eyi tunmọ si pe Johanu fẹ ki Ọlọrun jẹ ki ọrẹ rẹ ji pepe nipa ti ẹmi. Ko fẹ ki o kan jẹ aláásìkí ati alara-pipe eniyan ti o n gbe igbe aye alaiwa-bi-ọlọrun, igbe aye omugọ tabi igbe aye ti ko nitunmọ. Emi naa ko wa fẹ ki iwọ naa kan jẹ aláásìkí ati alara-pipe eniyan ti o n gbe igbe aye aibikita tabi igbe aye alaiwulo ninu ọdun yi. Idi si ni yi ti adura mi fun iwọ naa ni pe ki Ọlọrun jẹ ki o ji pepe nipa ti ẹmi ni gbogbo ọna ninu ọdun yi, ki o ba a le lo ilera ati ọrọ rẹ lati buyi fun un.

Ni kukuru, awọn adura mi fun ọ ni iwọnyi, bi a ti ṣe n bẹrẹ ọdun yi. Bi mo si ti ṣe n foju-sọna lati gbe oniruuru nkan nla ṣe pẹlu rẹ ninu ọdun naa, njẹ ki oore-ọfẹ Jesu Kirisiti Oluwa wa, ifẹ Ọlọrun ati idapọ Ẹmi mimọ wa pẹlu rẹ lati isinsinyi lọ ati titi lailai. Amin.

A kú ọdún tuntun o.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Àdúrà mi fún ọ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Sẹrẹ 05, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 36 Read More »