Fi ìfẹ́ rẹ han si | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èrèlé 23, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 43
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu idunnu ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o pari oṣu Èrèlé 2025. Adura mi si ni pe ninu ọsẹ naa ki Ọlọrun pese ohun rere gbogbo ti ọkan rẹ n fẹ lati ni ninu oṣu yi ti ko i ti tẹ ọ lọwọ fun ọ. Amin.
Wayi o, bi a ti ṣe n bẹrẹ ọsẹ tuntun yi, mo fẹ gba ọ niyanju pẹlu ọrọ Iwe mimọ yi nipa Solomọni ati bi o ti ṣe fi ara rẹ han gẹgẹ bi ẹni ti o yẹ fun ojurere Ọlọrun:
“Solomọni si fẹ Oluwa, o si nrin nipa aṣẹ Dafidi baba rẹ: ṣugbọn kiki pe, o nrubọ, o si fi nfi turari jona ni ibi-giga. Ọba si lọ si Gibeoni lati rubọ nibẹ; nitori ibẹ naa ni ibi-giga nlanla: ẹgbẹrun ọrẹ ẹbọ-sisun ni Solomọni ru lori pẹpẹ na.” (1Àwọn Ọba 3:3-4)
Ọna wo ni Solomọni gba fi ifẹ rẹ han si Ọlọrun, bi a ti ṣe ri ninu ẹsẹ bibeli yi? Akọkọ, o fi han nipa ririn ni ibamu pẹlu awọn aṣẹ iwa-bi-Ọlọrun ti baba rẹ pa fun. Eyi jasi pe o n rin ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun. Ekeji, o fi ifẹ rẹ han si Ọlọrun nipa fifi fun un. O fun ni ẹgbẹrun kan ọrẹ ẹbọ-sisun ni ọjọ kan. Ko si si akọsilẹ ninu bibeli ẹnikẹni fi ifẹ rẹ han si Ọlọrun ni irufẹ ọna yi ṣaaju asiko yi.
Ni kukuru, nitoripe Solomọni gbe ifẹ rẹ fun Ọlọrun kọja ọrọ ẹnu lasan nipa ririn ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ ati nipa lila ọwọ si i, Ọlọrun naa fi ara han loju ala lati san an ni ẹṣan. Ọlọrun ni ki o bere ohun yowu ti o ba fẹ ki Oun ṣe fun un. Bayi si ni o ṣe di ẹni ti o gbọn ju, ti o si tun lọrọ ju gbogbo awọn eniyan igba aye rẹ lọ. (Wo: 1Àwọn Ọba 3:5-12; 2Kíróníkà 1:1-12)
Ki ni eyi n kọ wa? O n kọ wa pe ko to fun wa lati ma a sọ fun Ọlọrun pe a nifẹ rẹ tabi lati ma sọ fun awọn eniyan pe a nifẹ Ọlọrun; a tun nilo lati ma fi ojoojumọ fi ifẹ ti a ni si i han. Bawo si ni a ṣe le fi ifẹ wa si i han? Akọkọ, a le fi han nipa ririn ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ. Ẹni yowu ti ko ba ni rin ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun ko gbọdọ sọ wipe, “Mo nifẹ Ọlọrun.” Irọ lasan ni eyi yoo jẹ. Tí o ba fẹran rẹ nitootọ, ko kan ki i ṣe wipe o o fi ara rẹ jin lati mọ ohun ti O fẹ nikan, nṣe ni o o tun ma ṣe ohun ti O fẹ.
Ọna keji lati fi han pe a nifẹ Ọlọrun ni nipa lilawọ si i. Ṣe a le sọ wipe a nifẹ enikẹni ti a ko ba lawọ si? Rara! Ti a ba nifẹ eniyan, a o ma la ọwọ si wọn. A o fẹ fun wọn ni ohunkohun ti o ba wa ni ikawọ wa lati mu inu wọn dun. Ki a tilẹ sọ otitọ, nigbamiran, nitori ifẹ wa fun awọn kan, a le ṣe kọja agbara wa lati fifun wọn. Ti ba si wa nifẹ Ọlọrun naa nitootọ, a o ri awọn asiko ti a o ṣe kọja agbara wa lati fifun un.
Arabinrin kan fi igba kan fi ifẹ rẹ si Jesu han nipa dida odidi igo ororo ikunra olowo-iyebiye kan si lori. Awọn ti o ri eyi si binu si gidigidi. Ki ni idi? Wọn woye wipe ororo ikunra yi ti wọn ju nkan ti ẹnikan kan le fi ṣofọ bẹyẹn lọ. Ṣugbọn lẹsẹkẹsẹ naa ni jesu sọ fun wọn pe ohun ti obinrin yi ṣe ko ki i ṣe fifi nkan sọfo rara. Dipo bẹẹ, o ṣe ohun ti o ṣe lati fi ifẹ rẹ han si i ni. Yatọ si iyẹn, o ṣe ohun ti o ṣe, gẹgẹ bi Oluwa ti ṣe sọ, lati pese agọ ara oun fun isinku ni, bi arabinrin funrarẹ ko tilẹ mọ eyi saaju asiko naa. O wa tunmọ si pe Ẹmi Ọlọrun ni O dari rẹ lati ṣe ohun ti o ṣe. Ere rẹ si ni pe gbogbo ibi ti a ba ti waasu iyinrere Oluwa ni a o ti ma darukọ rẹ. (Wọ: Mátíù 26:6-13; Máàkù 14:1-9; Jòhánù 12:1-8)
Nitorina, a tilẹ le sọ wipe ọkan lara ọna lati mọ bi a ti ṣe fi ara wa jin fun Ẹmi Ọlọrun to ni nipa lilawọ wa si Ọlọrun. Bawo wa ni o ṣe lawọ si i to? Bawo ni o ṣe lawọ si awọn iranṣẹ rẹ to? Bawo si tun ni o ṣe fi ara rẹ jin lati ma gbe igbe aye ti o dun mọ ninu to? Awọn nkan ti yoo jẹ ki a mọ boya o nifẹ rẹ lotitọ tabi o ko ni ni wọnyi. Adura mi ni pe ohun ti o pe ni ifẹ si Ọlọrun yoo ma fi igba gbogbo jẹ ojulowo dipo gbarọgudu, ni orukọ Jesu. Amin.
Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.
Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)



