A lè yí ọkàn Ọlọ́run padà | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 27, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 52
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu idunnu ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o so oṣu Igbe ati Ebibi 2025 papọ mọra wọn. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun tun ọ ṣe ni ibi yowu ti o ba ti n kuna laye, ki gbogbo ete rere rẹ fun ọ ba a le jẹ mimuṣẹ lalai si idena. Amin.
Ọkan lara awọn nkan ti a kọ́ ninu bibeli ni pe ironupiwada otitọ le e yi ọkan Ọlọrun pada. Ṣugbọn a wa ni awọn ọrọ Iwe mimọ ti o sọ fun wa pe Ọlọrun ki i yi ọkan rẹ pada. Eyi tunmọ si pe ti O ba ti pinnu lati ṣe nkan, ko si ohunkohun ti o le di lọwọ lati ṣe e. Ki wa ni ki a ṣe pẹlu irufẹ awọn ẹsẹ Iwe mimọ yi? Ṣe ki a pa wọn ti gẹgẹ bi eyi ti ko wulo ni? Ki a ma ri! A ko le pa ẹsẹ Iwe mimọ kankan ti gẹgẹ bi eyi ti ko wulo. Idi si nipe ko si ẹsẹ Iwe mimọ ti ko wulo. Dipo bẹẹ, gbogbo ẹsẹ Iwe mimọ ni o ti ọdọ Ọlọrun wa, ti o si wulo fun igbero wa. (Wo: Númérì 23:19; 1Sámúẹ́lì 15:29; 2Tímótì 3:16-17)
Amọ ṣa o, bi o tilẹ jẹ wipe a ni awọn ẹsẹ Iwe mimọ ti o sọ fun wa pe Ọlọrun ko ki i yi ọkan rẹ pada, a tun ni awọn ẹsẹ Iwe mimọ miran ti awọn naa n fi awọn nkan ti o le yi Ọlọrun lọkan pada han wa. Ọkan lara awọn nkan naa ti o si le jẹ ki O yi ọkan rẹ pada, bi mo ti ṣe sọ siwaju, ni ironupiwada otitọ. Fun apẹrẹ, Ọlọrun ni igba kan ran Wolii Elija si Ahabu lati ṣe idajọ oun ati ile rẹ fun pipa Naboti, ọkunrin alaiṣẹ kan. Ọlọrun sọ wipe Oun yoo pa gbogbo idile ọba yi run, Oun o si tun fi ẹran wọn fun awọn aja ati ẹyẹ jẹ. (Wo: 2Àwọn Ọba 21:17-24)
Wayi o, bi a ti ṣe ri ninu bibeli, Ahabu jẹ ọba kan ti o buru pupọ, ti o si tun gberaga. Yatọ si eyi, arabinrin ti o fẹ, iyẹn Jesebẹli, tun wa buru ju oun alara gan lọ. Awọn mejeji yi si wa mu ijọba ẹru wa sori awọn eniyan Ọlọrun. Sibẹsibẹ, nigba ti ọkunrin yi gbọ ọrọ idajọ Ọlọrun, ko ni ki a ra Elija ko, ko bẹrẹ si ni bu u tabi ki o ma ba yan odi. Ko tilẹ ba jiyan lori ọrọ naa. Dipo bẹẹ, nṣe ni o rẹ ara rẹ silẹ, ti o fa aṣọ rẹ ya, ti o wọ aṣọ ọfọ, ti o si tun gba ààwẹ̀. (Wo: 1Àwọn Ọba 21:17-27)
Ki wa lo jẹ ki Ahabu ṣe bayẹn? Idi ni pe o mọ wipe oun jẹbi. O mọ wipe ko si awawi fun pipa ọkunrin alaiṣẹ kankan. Nitorina, nkan ti o tọ ni fun Ọlọrun lati ṣe idajọ rẹ ni ibamu pẹlu iṣẹ ọwọ rẹ. Nkan kan ti o kan le fi ireti rẹ sinu rẹ ni aanu. Ọna kan ṣoṣo fun lati si ri aanu Ọlọrun gba ni ki o rẹ ara rẹ silẹ, ki o si gba ẹṣẹ rẹ gẹgẹ bi ẹṣẹ. Aijẹbẹ, idajọ ti a ti ṣe fun oun ati idile rẹ di dandan ki o wa sori wọn.
Wayi o, ṣe Ọlọrun, ni asiko yi, wa fi aanu ati idariji fun Ahabu bi tabi ko fi fun un? O fi fun un. Bibeli sọ wipe, “Nigba naa ni ọrọ Oluwa si tọ Elijah ara Tiṣibi wa wi pe, “Njẹ iwọ ti ri bi Ahabu ti rẹ ara rẹ silẹ niwaju mi? Nitori ti o ti rẹ ara rẹ silẹ, emi ki yoo mu ibi naa wa ni ọjọ rẹ, ṣugbọn emi yoo mu u wa si ile rẹ ni ọjọ ọmọ rẹ.” (1Àwọn Ọba 21:28-29)
Njẹ o ri bayẹn? Nitoripe Ahabu gba ẹṣẹ rẹ lẹṣẹ, Ọlọrun sun ọjọ ibi ti O fẹ mu wa sori oun ati ile rẹ siwaju di awọn ọjọ awọn ọmọ rẹ. Eyi ja si pe Ọlọrun yi ọkan rẹ pada fun igba diẹ. Ti awọn ọmọ Ahabu naa ba wa lọ pa ẹṣẹ rẹ ti ni, ti wọn si rẹ ara wọn silẹ niwaju Oluwa, idajọ ti O pasẹ le wọn lori ko ba ma ti waye ni awọn ọjọ wọn. Ki a tilẹ sọ otitọ, Ọlọrun gan an tilẹ le pa ipinnu rẹ lati ṣe idajọ idile wọn rẹ. Ṣugbọn wọn ko yipada kuro ninu ẹṣẹ baba wọn. Nitorina, a pada pa gbogbo wọn run ni, gẹgẹ bi Ọlọrun ti ṣeleri. (Wo: 2Àwọn Ọba 9)
Ki a ma fọrọgun, koko nkan ti a n sọ naa ni pe a le yi ọkan Ọlọrun pada nipasẹ ironupiwada otitọ. Nitorina, ti o ba yẹ Ọlọrun fi iya jẹ ọ fun nkankan ti o n ṣe ti ko dara, o le jẹ ki O yi ọkan rẹ pada nipa rironupiwada nitootọ. Ṣugbọn ti o ba tẹsiwaju lati ma a rin ninu igberega si i, ti o si kọ lati gba ẹṣẹ rẹ tabi aṣiṣe rẹ ni ẹṣẹ, idajọ rẹ le wa sori ri ki o to mọ nkan ti o n sẹlẹ. Ta wa ni o mọ bi eyi ṣe le buru fun ọ to. Nitorina, rẹ ara rẹ silẹ bayi, ki o si ronupiwada kuro ninu ẹṣẹ rẹ. Njẹ ki o ri okun ninu rẹ lati ṣe bẹẹ gẹgẹ. Amin.
Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.
Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)



