June 2025

Òun nìkan ní Ó ní agbára àṣepé | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òkúdù 29, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 9

Olufẹ: Ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o so oṣu Òkúdù ati oṣu Agẹmọ 2025 papọ mọ ara wọn. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ṣe ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu aye rẹ ni aṣepe, bi a ti ṣe n wọ inu abala keji ọdun yi ninu ọsẹ naa. Amin.

Dafidi, ninu ọkan ninu awọn saamu rẹ, sọ wipe, “Oluwa yoo ṣe ohun ti n ṣe temi laṣepe; Oluwa, aanu rẹ duro laelae; Ma ṣe kọ iṣẹ ọwọ ara rẹ silẹ.” (Sáàmù 138:8) Tani yoo ṣe ohun ti o ni i ṣe pẹlu Dafidi ni aṣepe? Oluwa! Ki ni idi! Idi ni pe Oun nikan ni O ni agbara aṣepe lọwọ. Ti ko ba wa ṣe awọn nkan ti o ni i ṣe pẹlu aye wa ni aṣepe, ko si ohun yowu ti a le ṣe lati ṣe aye wa ni aṣepe ti yoo ṣiṣẹ.

Ṣe a wa nilo aṣepe ni abala aye wa kankan bi? Ti a ko ba wa mọ tabi lero pe a nilo aṣepe ni abala aye wa kan, a ko ni pongbẹ fun un tabi gbe igbesẹ lati lọ fun un. Dafidi, fun apẹrẹ, ri kedere pe oun nilo aṣepe in awọn abala aye oun kan ni asiko ti o kọ saamu yi. Lotitọ, Ọlọrun ti fun ni ipo ẹyẹ, ibalẹ-ọkan, ilera ti o peye ati ọrọ. Ṣibẹsibẹ, o si tun ri wipe awọn nkankan si wa ninu aye, ile ati ijọba rẹ ti o nilo ki a tun wọn ṣe, ki a si tun ṣe wọn ni aṣepe. Eyi ti yoo fi wa ko ọkan soke lori awọn nkan wọnyi tabi ti yoo maa lakaka lati mojuto wọn funrarẹ, nṣe ni o fa wọn le Ọlọrun lọwọ, ti o si sọ wipe, “Oluwa yoo ṣe ohun ti n ṣe temi laṣepe.”

Nibakana, awa naa kọkọ gbọdọ ṣe idamọ awọn nkan ti o nilo aṣepe ninu aye wa, bi o ti wu ki nkan ma dun fun wa to lọwọlọwọ yi. Aijẹbẹ, a ko ni ri idi ti a fi nilo lati fa wọn le Ọlọrun lọwọ, ẹnikanṣoṣo ti O ni agbara aṣepe lọwọ. Siwaju si, lẹyin igba ti a ba ti ṣe idamọ awọn nkan naa ti o nilo aṣepe ninu aye wa, a ko gbọdọ gbiyanju lati mojuto wọn pẹlu ọgbọn tabi okun wa. Dipo bẹẹ, nṣe ni ki a fa wọn le Ọlọrun lọwọ.

Ki ni idi ti a fi gbọdọ ṣe eyi? Idi, bi mo ti ṣe sọ tẹlẹ, ni wipe a ko ni agbara aṣepe lọwọ. Ọlọrun nikan ni O ni lọwọ. Ti a ba si wa tiraka lati ṣe bi Ọlọrun ni ṣiṣe awọn nkan ti o ni ṣe pẹlu aye wa ni aṣepe, bi o ti wu ki awọn nkan wọnyi rọrun to loju, ko ni pẹ rara ti a o fi ri wipe a ti jẹ ki nkan burúkú di bùrùkù mọ ara wa lọwọ.

Ranti Ọba Jeroboamu. Ranti wipe Ọlọrun ni O yan gẹgẹ bi ọba lori orilẹ-ede Isiraẹli. Ṣugbọn nigba ti o ri wipe awọn nkankan le pa ijọba oun lara, ko tọ Ọlọrun lọ lati ṣe iṣẹ ti O bẹrẹ ninu aye rẹ laṣepe. Nṣe ni o darale ọgbọn ara rẹ. Nitorina, o mu iparun wa sori ara rẹ, sori ile rẹ ati sori orilẹ-ede naa lapapọ. (Wo: 1Àwọn Ọba 11-14)

Wayi o, mo wa gbadura wipe a ko ni mu iparun wa sori ara wa tabi sori awọn miran ni ayika wa ninu igbiyanju wa lati ṣe awọn nkan ti o ni i ṣe pẹlu aye wa ni aṣepe. Amọ a gbọdọ kọ lati ma ko aye wa ati ọrọ aye wa le Ọlọrun lọwọ ninu adura fun aṣepe wọn. Idi si ni pe ọ̀rọ̀ wa jẹ ẹ logun, O si tun ni agbara lati ṣe ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu wa ni aṣepe.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Òun nìkan ní Ó ní agbára àṣepé | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òkúdù 29, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 9 Read More »

Má ṣé ọkàn rẹ lè | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òkúdù 22, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 8

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o kẹyin oṣu Òkúdù 2025. Adura mi si ni pe ki eti rẹ ma ṣe lailai di si ohunkohun ti Ẹmi Ọlọrun ba n sọ fun ọ, ki o ba a le ma a fi igba gbogbo wa ni ailewu lati gbe igbe aye ti Ọlọrun fẹ ki o gbe. Amin.

Ninu iwe Heberu, oru ikẹta, a fun wa ni ikilọ yi: “Nitori naa gẹgẹ bi Ẹmi Mimọ ti wi: “Loni-in bi ẹyin ba gbọ ohun rẹ, Ẹ ma ṣe ṣe ọkan yin le…”” (Hébérù 3:7-8) Tani o n ba wa sọrọ nibiyi? Ẹmi Mimọ ni! Ki si ni O n ba wa sọ? O n sọ fun wa pe nigba ti oni ba si n jẹ oni, a ko gbọdọ ṣe ọkan wa le ti Ọlọrun ba n ba wa sọrọ. Eyi tunmọ si pe a ko gbọdọ sọ pe dandan lai ifẹ inu wa ni a o ṣe, nigba ti Ọlọrun tilẹ ti sọ fun wa ohun ti O fẹ ki a ṣe.

Njẹ ki wa ni idi ti ko fi yẹ ki a ṣe ọkan wa le ti Ọlọrun ba n ba wa sọrọ? Idi ni pe ṣiṣe eyi di dandan ki o yọri si idojuti, inira tabi iparun fun wa. Ranti nkan ti a sọ ninu bibeli nipa Farao ti o kọ lati jẹ ki awọn ọmọ Isiraẹli jade lati lọ sin Ọlọrun. A sọ wipe ọba yi ṣe ọkan rẹ le, o si kọ lati ṣe ohun ti Ọlọrun pa lasẹ. Lemọlemọ ni o n kọ eti didi si nkan ti Ọlọrun n sọ fun. Bawo wa ni ọrọ naa ṣe yọri si fun oun ati awọn eniyan rẹ? O yọri si nkan ti ko dara rara-rara ni. (Wo: Ẹ́kísódù 8:15:32)

Amọ ṣa o, ẹnikan le wa sọ wipe, “Ṣebi Ọlọrun funrarẹ ni O ṣe ọkan Farao le. Ṣe o wa yẹ ki ẹnikẹni ru ẹbi le lori bi?” Otitọ ni pe Ọlọrun ni O ṣe ọkan ọkunrin yi le. Ki si ni idi ti O fi ṣe bẹ ẹ? Akọkọ, O ṣe bẹ ẹ nitoripe ọkunrin naa funrarẹ ko fi igba kankan ṣetan lati gbọ nkan ti Ọlọrun ni lati ba a sọ. Eyi si n fi han wa pe aiṣetan wa lati gbọ nkan ti Ọlọrun n ba wa sọ di dandan ki o yọri si iṣele ọkan wa. Eyi tunmọ si pe igbakigba ti a ba yan lati kọ eti didi si nkan ti Ọlọrun n ṣọ fun wa, nṣe ni ọkan wa yoo jẹ ṣiṣe le si otitọ rẹ si i. Yoo wa ma ṣoro si fun wa lati ronupiwada ati lati gba ara wa kuro lọwọ idajọ rẹ. (Wo: Ẹ́kísódù 9:12; Ẹ́kísódù 10:20&27)

Idi miran ti Ọlọrun tun ṣe ṣe ọkan Farao le ni lati kọ wa pe Oun nikan ni O ni agbara lati jẹ ki awọn eniyan ronupiwada. Ti ko ba si lo agbara yi lati jẹ ki wọn ronupiwada, ko si nkankan ti a le sọ fun wọn tabi ṣe fun wa ti yoo jẹ ki wọn ronupiwada. Ranti pe igbakigba ti idajọ Ọlọrun ba wa sori Ijibiti nitori orikunkun Farao, nṣe ni yoo sọ fun Mose pe ki o ṣipẹ si Ọlọrun fun oun ati awọn eniyan rẹ. Ṣugbọn ni kete ti o ba ti ni iriri itura diẹ, nṣe ni yoo tun ṣe ọkan rẹ le lẹẹkan si.

Nitorina, nini iriri didara tabi aanu Ọlọrun ni ọna ti o ga ko to lati jẹ ki ẹnikẹni gbọran si lẹnu. Oun funrarẹ ni lati ṣiṣẹ lori ọkan wa lati jẹ ki a gbọ nkan ti O n sọ fun wa. Aijẹbẹ, bi O tilẹ fi wa sinu Edeni, bi O ti ṣe fun Adamu ati Efa, a o tun ṣe ọkan wa le si, ti a o si taari rẹ lati le wa jade kuro nibẹ.

Idi wa niyi ti o fi jẹ pe, bi o ti ṣe n lọ lọsẹ yi, o nilo lati kọ lati ma a fi ojoojumọ gbadura pe ki Ọlọrun ma jẹ ki o ṣe ọkan rẹ le si ohun yowu ti O ba n sọ fun ọ. Nipa bayi, iwọ yoo le ma fi igba gbogbo wa ni ailewu lati jẹgbadun didara ati aanu rẹ ni aye.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Má ṣé ọkàn rẹ lè | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òkúdù 22, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 8 Read More »

Dídá olùtùnú rẹ mọ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òkúdù 15, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 7

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Òkúdù 2025. Adura mi si ni pe ki o gba itunu Ẹmi Ọlọrun lẹkunrẹrẹ nibikibi ti ara ba ti n ni ọ tabi ti irẹwẹsi ba ti ba ọkan rẹ. Amin.

Wayi o, ọkan lara ọna ti Ọlọrun ma n gba tu wa lara ni asiko idanwo tabi idojukọ ni nipa riran awọn eniyan lati ṣe awọn nkan ti yoo tu wa lara fun wa. Fun apẹrẹ, Pọọlu sọ eyi fun awọn ara Kọrinti nipa bi Ọlọrun ṣe tu wọn lara nigba ti wọn wa ni Makedonia:

“Nitori pe nigba ti awa tilẹ de Makedonia, ara wa ko balẹ, ṣugbọn a n pọn wa loju niha gbogbo, ija n bẹ lode, ẹru n bẹ ninu. Ṣugbọn ẹni ti n tu awọn onirẹlẹ ninu, ani Ọlọrun, o tu wa ninu nipa dide Titu de.” (2Kọrinti 7:5-6)

Njẹ o ri bayẹn? Pọọlu jẹ ki o ye wa yekeyeke pe nkan ko rọgbọ fun oun ati awọn akẹgbẹ rẹ rara nigba ti wọn n waasu iyinrere ni Makedonia. A yọ wọn lẹnu, a si tun pọn wọn loju ni ibi gbogbo ti wọn ya si. Eyi jasi pe gbogbo igba ni wọn fi n wa ni bebe iyọnu. Nitorina, ifoya ko jina si wọn rara.

Bawo wa ni Ọlọrun ṣe mojuto wọn ni asiko naa, ti nkan ko fi su wọn, ki wọn si sọ ireti nu? Nipa riran Titu, ọkan lara awọn akẹgbẹ wọn ninu iṣẹ iranṣẹ, si wọn ni. Ki wa ni Titu ṣe fun wọn nigba ti o de ọdọ wọn? Pọọlu ko mẹnuba nkan ti o ṣe ninu akọsilẹ naa. Ṣugbọn o sọ fun wa pe Ọlọrun lo wiwa ọkunrin naa lati tu wọn lara. Nitorina, bi o tilẹ jẹ wipe irẹwẹsi ti ba wọn ki o to de, wiwa rẹ fun ọkan wọn ni itura ati isọdọtun.

Nibakanna, Ọlọrun le ran awọn eniyan sinu aye wa lati tu wa lara ati lati gbe wa soke ninu awọn idanwo wa. Ṣugbọn njẹ a o da wọn mọ bi? Ti Pọọlu ko ba da Titu mọ gẹgẹ bi olutunu ti Ọlọrun ran lati tu wọn ninu ati lati gbe wọn soke ni Makedonia, njẹ ko ni padanu itunu ti o mu wa bi? Nṣe ni ko ba padanu rẹ. Lotitọ, oun ati awọn yoku le ti ma gbadura si Ọlọrun fun itura ninu gbogbo awọn idanwo wọn ni asiko naa. Ṣugbọn ti wọn ko ba da ẹni ti Ọlọrun ran lati tu wọn lara mọ, ti wọn ba kan lọ ri wiwa rẹ bi iṣọnu lasanlasan, nṣe ni wọn ko ba padanu idahun si adura wọn.

Nitorina, ọtọ ni ki Ọlọrun ran olutunu si wa ni idahun si adura wa; ọtọ ni ki awa naa da wọn mọ, ki a si fi aye gba wọn lati tu wa ninu. Ọkan lara awọn idi ti ọpọ ninu awọn ọmọ Ọlọrun ko ki i ṣe gbadun itunu rẹ ninu aye wọn bi o ti ṣe yẹ ni pe wọn ko da awọn ti o ran lati tun wọn ninu mọ. Ki ni idi? Idi kan pataki ni pe awọn eniyan wọnyi naa ni aleebu ti ara wọn. Nitorina, wọn le ni awọn iwa ti yoo rin awọn miran lara tabi ti yoo bi wọn ninu tabi ti yoo ṣi wọn lọna. Ti a ba si wa gbajumọ kiki awọn nkan ti ko dara ninu aye wọn, a le pada pa wọn ti, bu wọn tabi fi idibajẹ sinu aye wọn, ki a si padanu itunu ti Ọlọrun ran wọn lati fi fun wa.

Idi si ni yi ti a ṣe gbọdọ kọ lati ma gbadura si Ọlọrun lati ma fi igba gbogbo da awọn ti O n ran lati tu aye wa lara ati lati gbe wa soke mọ, ki a ba a le ba wọn ṣe pọ ni ọna ti o tọ, ki a si jẹ igbadun itunu ti wọn mu wa lẹkunrẹrẹ. Njẹ ki o gba okun lati ma fi ojoojumọ mu eyi ni pataki, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Dídá olùtùnú rẹ mọ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òkúdù 15, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 7 Read More »

Ìgbàgbọ́ tó múra sílẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òkúdù 08, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 6

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. O dun mọ mi ninu lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ keji oṣu Okudu 2025. Mo si gbadura pe ki ọkan rẹ maa fi igba gbogbo wa ni imurasilẹ lati tẹwọgba lọwọ Ọlọrun ohun rere gbogbo ti O fẹ ki o ni. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ẹnikẹni ko le ri ohun rere kankan gba laye yi, ti ko ba jẹ wipe Ọlọrun ti pese ohun naa. Eyi jasi pe kiki nkan ti Ọlọrun ba fifun wa tabi pese nikan ni a le ri gba. Ti ko ba pese nkan, ko si ẹni naa, bi o ti wu ki igbagbọ rẹ ga to, ti o le ri ohun naa gba. (Wo: Jòhánù 3:27)

Amọ ṣa o, bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun ti pese nkan fun wa, awa naa nilo lati fẹ lati ni nkan naa. Aijẹbẹ,nkan naa le ma lailai jẹ ti wa, ayaafi ti a ba ṣaanu fun wa. Fun apẹrẹ, bi a ti ṣe ri ninu bibeli, idile Sakaraya ati Elisabẹti wa ni ailọmọ fun ọpọlọpọ ọdun, bi o tilẹ jẹ wi pe olododo ni wọn jẹ niwaju Ọlọrun. Eyi ko si wa jẹ ki wọn yipada tọ oriṣa kankan lọ. Dipo bẹẹ, nṣe ni wọn tẹsiwaju lati ma a gbadura si Ọlọrun lati ṣaanu fun wọn ati lati mu ẹgan wọn kuro. (Wo: Lúùkù 1:5-7)

Njẹ bawo ni mo ṣe wa mọ pe wọn n gbadura si Ọlọrun lati mu ẹgan airọmọbi kuro ninu ile wọn? Mo mọ nitoripe, bi a ti tun ṣe ri ninu bibeli, nigba ti Ọlọrun ran angẹli Geburẹli lati fun wọn ni iyinrere idahun si adura wọn, nkan akọkọ ti o sọ fun Sakaraya ni pe, “Adura rẹ ti gba.” Nitorina, ti a ko ba rẹwẹsi ni gbigbadura si Ọlọrun, o di dandan ki a ri idahun gba si adura wa, niwọn igba ti o ba ti wa ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ. Lotitọ, idahun naa le gba asiko diẹ ki o to de ọdọ wa. Ṣugbọn o di dandan ki o de. (Wo: Lúùkù 1:13)

Amọ ṣa o, njẹ idahun Ọlọrun si awọn adura wa yoo ba wa ni imurasilẹ nigbagbo bi? Njẹ a o wa ni imurasilẹ lati tẹwọgba lọwọ Ọlọrun ohun naa ti O fẹ ki a ni, eyi ti awa gan naa ti le ma gbadura ati pongbẹ fun, nigba ti a ba pada mu nkan naa tọ wa wa? Sakaraya ko si ni imurasilẹ lati tẹwọgba lọwọ Ọlọrun ọmọ ti o ti n fi ọpọlọpọ ọdun gbadura fun nigba ti Ọlọrun pada la ọna fun ọmọ naa lati tọ ẹbi rẹ wa. Ko gbagbọ pe Ọlọrun le fun awọn ni ọmọ nitootọ ni ọjọ ogbo wọn. (Wo: Lúùkù 1:11-20)

Ki wa ni o n gbadura si Ọlọrun fun ọmọ fun ni gbogbo awọn ọdun wọnni? O dabi ẹni pe o kan n gbadura lati mu gbogbo ododo daju ni. Ti Ọlọrun ko ba wa ṣaanu fun, bi o tilẹ jẹ wipe ko gbagbọ, oun ni ko ba jẹ idi ti iyawo rẹ ko ba fi jade laye lalai lọmọ.

Nitorina, adura gbigba si Ọlọrun lati fun wa ni nkan ko to. Ọkan wa tun gbọgbọ ma fi igba gbogbo wa ni imurasilẹ lati tẹwọgba nkan ti a n gbadura fun lọwọ rẹ, bi o ti wu ki idahun si adura naa pe to ati bi o ti wu ki o dabi enipe o ṣoro fun idahun si adura naa lati tẹ wa lọwọ. Aijẹbẹ, adura wa fun nkan naa le pada jasi pabo.

Yatọ si eyi, a gbọdọ ma a fi igba gbogbo fi ara wa jin fun ọrọ Ọlọrun, ki igbagbọ wa ba a le gba okun lati ma fi igba gbogbo wa ni imurasilẹ lati ri nkan gba lọwọ rẹ. Maria iya Jesu, fun apẹrẹ, ko fi igba kankan gbadura si Ọlọrun lati di iya olugbala araye. O tilẹ ṣeeṣe ki o ma fi igba kankan gbe yẹwo tabi ka si babara ẹṣẹ Iwe mimọ ti o sọrọ nipa wundia kan ti yoo loyun, ti yoo si bi olugbala. Ṣugbọn nigba ti angẹli Geburẹli wa lati sọ fun pe oun ni Ọlọrun yan lati jẹ iya olugbala, igbagbọ rẹ wa ni imurasilẹ lati tẹwọgba nkan ti Ọlọrun ti yan an fun. Nitorina, o sọ wipe, “Jẹ ki o ri fun mi gẹgẹ bi ọrọ rẹ.” O si ri bẹẹ. (Wo: Àìsáyà 7:14; Lúùkù 1:36)

Nibakanna, ti igbagbọ wa ba n fi igba gbogbo wa ni imurasilẹ lati ri gba lọwọ Ọlọrun, ohun yowu ti O ba fẹ ki a ni yoo jẹ ti wa, bi a ko tilẹ fi igba kankan ri gbadura fun un. Nitorina, nṣe ni ki a kọ lati ma a fi ojoojumọ bọ ara wa pẹlu ọrọ rẹ, ki a ba a le ma fi igba gbogbo ni igbagbọ to murasilẹ lati ri nkan gba lọwọ rẹ. Njẹ ki iwọ ati emi gba okun lati ṣe bẹẹ gẹgẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ tí o ga.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ìgbàgbọ́ tó múra sílẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òkúdù 08, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 6 Read More »