Àkórí: Àìmọ ǹkan tí ó kàn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Agẹmọ 27, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 13
Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati aanu di ilọpo-ilọpo fun ọ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o pari oṣu Agẹmọ 2025. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun ma a fi ojoojumọ jẹ ki o fi ọkan si awọn nkan ti o ṣe pataki lotitọ laye yi, ki o ma ba fi aye rẹ sofo lori awọn nkan ti ko ni itumọ. Amin.
Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, o ṣeeṣe ki a fi ara wa jin fun awọn nkan ti ko tọ, ki a si ro wipe Ọlọrun ni a n ṣe wọn fun. Eyi yoo si jẹ nitoripe a ko mọ bi a ti ṣe le mojuto nkan ni iwọn bi o ti ṣe ṣe pataki tabi bi o ti ṣe gbọdọ jẹ mimuṣe ni kiakia si. Nibiti eyi ba si ti ri bẹ, a le ri wipe a padanu awọn nkan ti o le mu iyipada ayeraye ba aye wa nibi ti a ba ti n sare le awọn nkan ti ko le fun wa ju igbadun asiko diẹ lọ.
Fun apẹrẹ, bibeli sọ nkankan ti o ṣẹlẹ nigba ti Jesu lọ si ile Maria ati Mata fun ibẹwo lọjọ kan. Wo bi Luuku ti ṣe royin rẹ ninu iwe iyinrere rẹ:
“O si ṣe, bi wọn ti n lọ, o wọ ileto kan, obinrin kan ti a n pe ni Mata si gba a si ile rẹ. O si ni arabinrin kan ti a n pe ni Maria ti o si jokoo lẹbaa ẹsẹ Jesu, ti o n gbọ ọrọ rẹ. Ṣugbọn Mata n ṣe iyọnu ohun pupọ, o si tọ ọ wa, o wi pe, “Oluwa, iwọ ko si bikita si ti arabinrin mi pe o fi mi silẹ lati maa nikan ṣe iranṣẹ? Wi fun n ki o ran mi lọwọ.” Ṣugbọn Jesu si dahun, o si wi fun un pe, “Mata, Mata, iwọ n ṣe aniyan ati laalaa nitori ohun pupọ. Ṣugbọn ohun kan ni a ko le ṣe alaini, Maria si ti yan ipa rere naa ti a ko le gba lọwọ rẹ.” (Lúùkù 38-42)
Ki ni akọsilẹ yi n fi han wa? O n fi nkankan han wa lori ki a ma mọ nkan ti o kan. Ta si ni ko mọ nkan ti o kan lọrọ rẹ ninu akọsilẹ naa? Mata ni. Lọna wo? Ṣe o ṣe nkan ti o buru nipa ṣiṣe iṣẹ karakara lati ṣe alejo Jesu ati awọn ọmọ ẹyin rẹ ni asiko yi ni? Rara o! Ṣugbọn ko ba tilẹ kọkọ fi aye silẹ lati ba Oluwa sọrọ ati lati gbọ ohun rẹ. Eyi ko ba si ran an lọwọ lati mọ ọna ti o tọ ati asiko ti o yẹ lati ṣe alejo rẹ.
Awọn die ninu wa naa si ma n ṣaba ṣe aṣiṣe kan naa ti awọn eniyan ba bẹ wa wo. A o ma kanju lati ṣe alejo wọn lalai kọkọ lo asiko diẹ lati ba wọn fọrọ jomitoro ọrọ ati lati mọ eredi ibẹwo wọn. A si wa ma le fi ara balẹ rara lati ba wọn sọ ọrọ pataki kankan titi wọn yoo fi lọ, nitoripe a ṣa a fẹ ṣe alejo wọn. Eyi ko ki i ṣe ọna ti o tọ lati gbe ibaṣepọ ti o dara, ti o si tun ni itumọ ro.
Ni kukuru, nigba ti Mata n ṣe akitiyan gidigidi lati ṣe alejo Jesu, nṣe ni arabinrin rẹ, Maria, joko lati kẹkọ lọdọ rẹ. Eyi si wa bi i ninu debi pe ko le pa a mọra. Nitorina, o tọ Jesu wa lati sọ fun pe ki O ba Maria wi fun bi ko ti ṣe mọ nkan ti o kan lọrọ rẹ, ki O si tun ran sọdọ oun lati ran an lọwọ ni pipese awọn nkan ti wọn yoo fi ṣe alejo ati Oun ati awọn ọmọlẹyin rẹ.
Ṣugbọn dipo ti Oluwa yoo fi ṣe nkan ti o fẹ, nṣe ni O sọ fun pe oun gan an ni ko mọ nkan ti o kan lọrọ rẹ. Eyi jasi pe, nṣe ni o yẹ ki oun pẹlu joko gẹgẹ bi arabinrin rẹ lati kẹkọ lọdọ rẹ. Igbana ni ko ba ni imọ ti o peye si lori bi o ti ṣe le ṣe alejo rẹ, ki o si gba oriyin. Imọ yi ko ba si wa jẹ tirẹ titi aye ni. Amọ o padanu anfaani rẹ lati kẹkọ ati lati di eniyan daradara si lọjọ naa. O ma ṣe o!
Ki a ma fọrọgun, koko ọrọ naa ni pe a ko gbọdọ fi aye gba ohun rere yowu ti a ba n ṣe fun Ọlọrun lati ma jẹ ki a kọbiara si i, si ọrọ rẹ ati si adura ni ọna ti o peye. Aijẹbẹ, a ko ni mọ ọ ati bi o ti ṣe tọ lati ṣin in si i. Eyi si le jẹ ki a padanu ere awọn nkan rere yowu ti a ro wipe a n ṣe fun un.
Nitorina, ẹ jẹ ki a ma fi igba gbogbo mọ nkan ti o kan lọrọ wa, gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun. Ibaṣepọ wa pẹlu rẹ gbọdọ ma fi gbogbo igba siwaju iṣẹ-isin wa si i. Njẹ ki ọkan wa gba okun lọna ti o peye lati ma ṣe lailai gbagbe nkan yi i. Amin.
Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.
Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

