August 2025

Yí ìrònú rẹ padà | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ògún 31, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 18

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọjọ ti o pari oṣu yi ati pẹlu sinu ọsẹ akọkọ ninu oṣu kẹṣan odun yi, iyẹn oṣu Owewe 2025. Adura mi ni pe ki Ọlọrun ri daju pe ohun rere gbogbo ti O ni ni ipamọ fun ọ ni awọn oṣu ti o ku ninu ọdun naa jẹ tirẹ lotitọ, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe n bẹrẹ ọsẹ tuntun yi, mo fẹ gbọ ọ niyanju pẹlu ọrọ Apọsiteli Pọọlu ti o sọ pe:

“Ki ẹ má si da ara nyin pọ̀ mọ́ aiye yi: ṣugbọn ki ẹ parada lati di titun ni iro-inu nyin, ki ẹnyin ki o le ri idi ifẹ Ọlọrun, ti o dara, ti o si ṣe itẹwọgbà, ti o si pé.” (Róòmù 12:2)

Ki ni idi ti o fi sọ fun wa pe ki a ma ṣe ba aye yi rẹ mọ? Idi naa ni pe a ti di ọmọ Ọlọrun. Ki a to di ọmọ Ọlọrun, nṣe ni a n gbe aye wa ni ibamu pẹlu irin awọn ẹni ti aye yi. A n sọrọ bi wọn ṣe n sọrọ. A n ronu bi wọn ti ṣe n ronu. A n mura bi wọn ti ṣe n mura. A si tun n le awọn nkan ti wọn n le.

Ṣugbọn nibayi ti a ti di ọmọ Ọlọrun, nṣe ni o yẹ ki a ma gba igbe aye ti o yatọ. Bẹẹni, nṣe ni o yẹ ki a ma gbe aye wa bi ọmọ Ọlọrun dipo bi ọmọ eṣu. A ko wa ni gbe aye wa yatọ si ti awọn ti aye yi niwọn igba ti a ba si n ronu bi wọn ti ṣe n ronu. A le ma lọ si awọn ipade ṣọọsi o, ki a ma gbadura ni orukọ Jesu ati ki a tilẹ tun ma gbe bibeli kaakiri. Ṣugbọn niwọn igba ti a ba si n ronu bi ti awọn ti aye yi, a ko ni gbe igbe aye ti o yatọ si ti wọn ninu isọrọ wa, imura wa ati bi a ti ṣe n ṣe si awọn miran.

Ṣe o ri, awọn eniyan ma n gbe aye wọn ni ibamu pẹlu ironu wọn ni. Nitorina, ti o ba fẹ ki wọn yi bi wọn ṣe n gbe aye pada, o o nilo lati yi bi wọn ti ṣe n ronu pada. Idi si ni yi ti Pọọlu ko kan ṣe sọ fun wa pe ki a ma ba aye yi rẹ mọ, o tun sọ fun wa pe ki a gba iyipada aye wa nipa titun ironu wa ṣe. Ki ni yoo mu iyipada ba aye wa? Yiyi ironu wa pada ni.

Bawo wa ni a ṣe le yi ironu wa pada? Bawo ni a ṣe le fọ ironu wa mọ, ki a ba le ma ronu yatọ si bi awọn ti aye yi ṣe n ronu? Nipa fifi ara wa jin fun ọrọ Ọlọrun ni. Bi a ba ṣe n fi ara wa jin fun ọrọ rẹ si naa ni a o ṣe bẹrẹ si ni ma a ronu yatọ si – a o bẹrẹ si ni ma a ronu ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ fun wa. Bi a ba si ṣe n ronu ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ fun wa si naa ni a o ṣe yirapada si lati da ẹni ti O fẹ ki a da.

Pọọlu, fun apẹrẹ, ti o fun wa ni ọrọ iyanju Ẹmi yi ti kọkọ fi igbakan ri jẹ aṣekupani ati ika eniyan. Sibẹsibẹ, o wa pada di ọkan lara awọn Kiristiẹni ti o ga julọ ti o ti gbe orilẹ-aye yi. Ki a tilẹ sọ otitọ, iriri iyipada ti aye rẹ ni da a loju debi wipe o le sọ fun awọn Kirisitiẹni miran pe ki wọn ma fi oun ṣe awokọṣe (1Kọ́ríntì 11:1). Bawo ni eyi ṣe ṣẹlẹ? O ṣẹlẹ lati ipasẹ ifarajin rẹ fun ọrọ Ọlọrun. Ọrọ Ọlọrun ni o yi ironu rẹ pada. Bi ọrọ Ọlọrun si ṣe n yi ironu rẹ pada naa ni aye rẹ n gba iyipada. Nigba ti o si wa to asiko kan, gbogbo awọn ti o wa ni ayika rẹ wa ri wipe o ti di ẹniyan ọtọ nitootọ – o ti dabi Kirisiti.

Wayi o, niwọn igba ti Pọọlu ti funrarẹ ni iriri awọn nkan wọnyi, o wa n sọ fun awa naa pe ki a ṣe amulo ọrọ Ọlọrun lati yi ironu wa pada. Bayi ni aye wa yoo ṣe gba iyipada lati jẹ nkan ti Ọlọrun fẹ ki wọn jẹ. Nitorina, fi ara rẹ jin fun ọrọ Ọlọrun ki o ba le yi bi o ti ṣe n ronu pada. Ki o si to mọ nkan ti o n ṣẹlẹ, aye rẹ yoo ti yipada lati da nkan naa ti Ọlọrun fẹ ki o da.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Yí ìrònú rẹ padà | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ògún 31, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 18 Read More »

Fà á lé Ọlọ́run lọ́wọ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ògún 24, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì PÁSÍTỌ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 17

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o kẹyin oṣu Ògún 2025. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun mojuto gbogbo ẹrù ti Satani n lepa lati lo lati pa ọ run tabi lati kun aye rẹ pẹlu inira. Àmín.

Ki ni idi ti mo fi gba adura yi fun ọ? Idi naa ni pe ko si ẹrù ti o n gbe ti Ọlọrun ko le mojuto fun ọ. Ki a tilẹ sọ otitọ, Ọlọrun ko fẹ ki o da gbe ẹrù aye rẹ kankan gbe funrarẹ. Nkan ti O fẹ ni pe ki O ba ọ gbe ọkọọkan ninu ẹrù rẹ fun ọ. Iwọ naa wo nkan ti Dafidi sọ lori eyi ninu ọkan ninu awọn saamu rẹ:

“Olubukun ni Ọlọrun, si Ọlọrun Olugbala wa, ẹni ti o n fi ojojumọ gba ẹru wa ru.” (Saàmù 68:19)

Njẹ o ri bayẹn? Bawo ni Ọlọrun ṣe n ba wa gbe ẹrù wa si? Ṣe fun igba diẹ ni? Rara o! Ṣe fun awọn ọsẹ tabi oṣu melokan ni? Rara o! Dipo bẹẹ, nṣe ni O n ba wa gbe ẹrù wa lojoojumọ. Ki si ni idi ti O fi n ba wa gbe wọn ni ojumọ kọọkan? Idi ni pe O fẹran wa, O si n fẹ ṣe ikẹ wa. (Cf. 1Pétérù 5:7)

O wa ṣeeni laanu pe ọpọ ninu wa ni ko mọ pe Ọlọrun ma n fi ojoojumọ gba ẹrù wa ru. A kan ro wipe awọn nkan rere ti o n ṣẹlẹ si wa laye kan ṣa dede n ṣẹlẹ ni ati wipe awọn nkan buruku ti ko ṣẹlẹ si wa ko ṣẹlẹ si wa nitori ododo, iwa-bi-Ọlọrun tabi ikiyesara wa. Ṣugbọn awọn nkan rere ti o n ṣẹlẹ si wa n ṣẹlẹ si wa nitoripe Ọlọrun n gba ẹrù wa ru ni. Nibakana, awọn nkan buruku ti ko ṣẹlẹ si wa ko ṣẹlẹ si wa nitoripe Ọlọrun n ṣiṣẹ fun aabo wa ni.

Amọ ṣa o, Ọlọrun fẹ ki a mọ daju-ṣaka pe idi ti awọn ẹrù ti aye n ju si wa ko ṣe ti pa wa run ni pe Oun n ba wa gba wọn ru. Nitorina, awọn ẹrù aye wa kan wa ti O le ma fi ọwọ kan rara ti ko ba ṣe wipe a mọ-ọn-mọ fa wọn le e lọwọ lati mojuto fun wa. Njẹ a o wa fa awọn ẹrù wa le lọwọ lati mojuto fun wa bi? Tabi nṣe ni a o tẹsiwaju lati ma tiraka lati gbe wọn funralara wa titi wọn yoo fi tẹ wa rẹ mọlẹ?

Fun ọpọ ọdun, Jakọbu n gbe ẹrù awọn ẹṣẹ rẹ si arakunrin rẹ, Isau, funralara rẹ. Diẹ si lo ku ki ẹrù naa tẹ rẹ mọlẹ. Ṣugbọn ni ọjọ ti o fa ẹrù naa le Ọlọrun lọwọ ninu adura gan-an naa ni o gba itusilẹ kuro lọwọ rẹ. Ọlọrun mojuto ẹrù naa ni ọna ti o jẹ wipe oun gan ko le sọ idi naa pato ti Isau, ti o ṣigun jade lati wa kọ lu oun ati idile rẹ, fi kan dede bẹrẹ si ni fi ifẹ han si, ti o si tun n sọ ọrọ itunu si. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 32-33)

Ni kukuru, eyi n fi han wa pe ti ko ba ṣe wipe a ba kọ lati ma a fa awọn ẹrù wa le Ọlọrun lọwọ ninu adura, a le ma mọ irufẹ itura ati ibalẹ-ọkan ti O le fi fun wa. Bẹẹni, o le dabi ẹni wipe ko si ẹnikẹni ayafi iwọ nikan ti o le ba ọ gbe ẹrù naa ti o n gbe fun ọ. Ṣugbọn okodoro ibẹ ni pe iwọ funrarẹ ko le gbe ẹrù kankan ti Ọlọrun ko ba ba ọ gbe. Nitorina, ma ṣe jẹ ki ẹrù kankan, boya ti ẹṣẹ, ibẹru, aini tabi aisan ni, pa ọ run. Dipo bẹ ẹ, fa a le Ọlọrun lọwọ. Idi si ni pe O fẹran rẹ, O si ti fi ara rẹ jin lati ma a gbe gbogbo ẹrù rẹ fun ọ ni ojoojumọ. Njẹ ki o ni iriri asiko itura ti o ga, bi o ti ṣe n ṣe eyi, ni orukọ Jesu. Àmín.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Fà á lé Ọlọ́run lọ́wọ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ògún 24, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì PÁSÍTỌ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 17 Read More »

Tọ́ ara rẹ sí ìwà-bí-Ọlọ́run | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ògún 17, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 16

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu ayọ ti o ga ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ògùn 2025. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ma a fi ojoojumọ fun ọ ni okun ninu ọsẹ naa ati ni gbogbo iyoku ọdun aye rẹ lati gbe igbe aye ti inu rẹ dun si gidigidi. Amin.

Bi a ti ṣe n bẹrẹ ọsẹ tuntun yi, mo fẹ gba ọ niyanju pẹlu awọn ọrọ Pọọlu wọnyi ti o sọ wipe:

“Ṣugbọn kọ̀ ọrọ asan ati itan awọn agba obinrin, si mã tọ́ ara rẹ si ìwa-bi-Ọlọrun. Nitori ṣíṣe eré ìdaraya ní èrè diẹ, ṣugbọn ìwa-bi-Ọlọrun li ère fun ohun gbogbo, o ni ileri ti aiye isisiyi ati ti eyi ti mbọ̀.” (1Tímótì 4:7-8)

Ki ni nkan akọkọ ti apọsiteli yi sọ fun wa? Oun naa ni pe ki a ma ṣe fi asiko wa ṣofo lori awọn itan ti ko gbe iwa-bi-Ọlọrun larugẹ ati ti ko wa ni ibamu pẹlu otitọ ti Ọlọrun n sọ fun wa. A si ni ọpọlọpọ irufẹ awọn itan yi lati aṣa kan de aṣa miran. Wọn dabi igba ti wọn n sọ otitọ lori aye nitoripe wọn ti di àtẹnudẹ́nu fun ọpọlọpọ iran awọn eniyan. Ṣugbọn wọn ko ki i ṣe otitọ rara, nitoripe wọn lodi si nkan ti Ọlọrun n sọ fun wa nipasẹ Iwe mimọ rẹ. Ti a ko ba si fẹ ki wọn pa aye ati ọkan wọn run, a gbọdọ takete si wọn.

Nkan ekeji ti Pọọlu sọ fun wa ninu awọn ẹsẹ bibile yẹn ni pe ki a tọ ara wa si iwa-bi-Ọlọrun. Ki ni idi? Idi akọkọ ni pe iwa-bi-Ọlọrun ki i ṣadede waye. Lotitọ, ọmọ Ọlọrun ni wa, a si tun ni nkan ti o n je ki eniyan gbe igbe aye iwa-bi-Ọlọrun ninu wa (2Pétérù 1:3). Amọ ti a ko ba fi ara fun awọn nkan ti yoo gbe iwa-bi-Ọlọrun larugẹ, iwa-bi-Ọlọrun ko ni jẹyọ ninu aye wa.

O wa ṣeni laanu pe ọpọ ọmọ Ọlọrun ni ko mọ eyi. Wọn ro wipe ti eniyan ba ti di atunbi, ṣadede ni awọn ti o wa ni ayika rẹ yoo bẹrẹ si ni ri bi ẹni-bi-Ọlọrun. Ṣugbọn eyi ko ri bẹ rara. Ti ẹni naa ki ba fi ara rẹ jin fun ọrọ Ọlọrun, fun adura gbigba ati ibaṣepọ pẹlu awọn eniyan Ọlọrun, iwa-bi-Ọlọrun ko ni jẹyọ ninu aye rẹ. Yatọ si iyẹn, ti ẹni naa ko ba bẹrẹ si ni mọ-ọn-mọ gbe igbesẹ lati ṣe awọn nkan ti o tọ ati lati yẹra fun awọn nkan ti ko tọ, awọn eniyan ko ni mọ si ẹni-bi-Ọlọrun. Nitorina, ti o ba fẹ ki awọn eniyan ri ọ gẹgẹ bi ẹni-bi-Ọlọrun, o nilo lati mọ-ọn-mọ bẹrẹ si ni tọ ara rẹ lati ma ṣe awọn nkan ti yoo gbe iwa-bi-Ọlọrun larugẹ ninu aye rẹ.

Idi miran ti Pọọlu tun ṣe sọ fun wa pe ki a tọ ara wa si iwa-bi-Ọlọrun ni pe awọn anfaani ti o sọrọ mọ pọ jọjọ. Awọn anfaani yi ko kan ki wa ṣe ti aye yi nikan; wọn tun jẹ anfaani ayeraye. Iwọ naa gba eyi ro: awọn iṣoro kan wa ti o ko le ni ninu aye yi, ti o ba n gbe igbe aye iwa-bi-Ọlọrun. Fun apẹrẹ, ti o ko ba ki i ṣe ọmọti, awọn irufẹ idojuti kan wa ti o ko le ni iriri wọn laye. Ṣugbọn ti o ba jẹ ọmọti, o di dandan ki o ma dojuti ara rẹ loore-koore.

Nitorna, ti o ko ba fẹ awọn iṣoro kan ninu aye rẹ, o kan nilo lati tọ ara rẹ si iwa-bi-Ọlọrun ni. Lafikun, ti o ba fan iyin Ọlọrun ninu aye yi ati nigba ti o ba de ọrun, nṣe ni ko o ma a fi ojoojumọ tọ ara rẹ si iwa-bi-Ọlọrun. Njẹ ki Ẹmi Ọlọrun fun ọ ni okun lati ṣe bẹ ẹ gẹgẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Tọ́ ara rẹ sí ìwà-bí-Ọlọ́run | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ògún 17, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 16 Read More »

Kò gbọdọ̀ jẹ́ fún ìgbà díẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ògún 10, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 15

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ògùn 2025. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun maa fi ojoojumọ kun ọkan rẹ pẹlu irẹlẹ, ki o ba a le tẹsiwaju lati ma ni iriri igbega rẹ ni gbogbo abala aye rẹ. Amin.

Lẹyin igba ti Ọba Sọọlu ti ṣe aigbọran si Ọlọrun nipasẹ pe ko pa gbogbo awọn ara Amaleki run, Samuẹli sọ eyi fun un:

“Iwọ kò ha kere loju ara rẹ nigbati a fi ọ ṣe olori ẹya Israeli, ti Oluwa fi àmi ororo sọ ọ di ọba Israeli?” (1Sámúẹ́lì 15:17)

Nigba wo ni Ọlọrun fi ami ororo sọ Sọọlu di ọba lori Isiraẹli? Ni igba ti o jẹ onirẹlẹ ni. Ni igba ti ko ri ara rẹ gẹgẹ bi ẹni ti o san ju awọn miran lọ ni. Ṣugbọn lẹyin igba ti a ti fi idi itẹ rẹ mulẹ tan, o fi aye gba igberaga ninu ọkan rẹ, o si bẹrẹ si ni ṣe bi o ti ṣe wu u.

Njẹ iha wo wa ni Ọlọrun kọ si eyi? O gba ijọba ti O fifun un kuro lọwọ rẹ. O si fi ọdọmọkurin kan, iyẹn Dafidi, rọpo rẹ. Bi o tilẹ wa jẹ wipe o ja fitafita lati pa ijọba naa mọ fun ara rẹ ati fun arọmọdọmọ rẹ, ko ri i pa mọ. Idi si ni pe kiki nkan ti Ọlọrun ba fun wa ni a le pa mọ fun ara wa. A ko le pa nkan ti O ba ti gba kuro lọwọ wa mọ fun ara wa.

Ni kukuru, koko itan bibeli yi naa ni pe irẹlẹ wa ko gbọdọ jẹ fun igba diẹ. Dipo eyi, nkan ti a gbọdọ ni lati ibẹrẹ de opin ni. Ti a ba fi irẹlẹ han niwaju Ọlọrun fun igba diẹ, nṣe ni igbesoke wa naa yoo wa fun igba diẹ. Eyi jasi pe, ni kete ti a ba ti bẹrẹ si ni fi igberaga han, Ọlọrun kanna ti O ti n gbe wa ga yoo bẹrẹ si ni ja wa bọ. (Wo: Jákọ́bù 4:6; 1Pétérù 5:5)

Eyi si wa ni idi ti awọn kan ko ti ṣe ga ju ipo ti wọn wa laye lọ. Nigba ti wọn rẹ ara wọn silẹ niwaju Ọlọrun, O ṣaanu fun wọn, O si bẹrẹ si ni gbe wọn ga. Ṣugbọn nigba ti wọn de awọn ipo nla kan, wọn bẹrẹ si ni ṣiwawu. Wọn bẹrẹ si ni ṣe bi igba ti o jẹ wipe ọgbọn tabi agbara wọn ni o gbe wọn de ibi ti wọn wa. Nitorina, dipo ki Ọlọrun gbe wọn lọ si ibi ti o ga ju ibi ti wọn wa lọ, nṣe ni O fi wọn silẹ sibẹ, ti O si bẹrẹ si ni gbe awọn miran ni ayika wọn ga. Ti wọn ba si wa tẹsiwaju lati ma a rin ninu igberaga, a le pada re wọn jabọ si awọn aye ti o kere ju ibi ti wọn wa lọ.

Nitorina, irẹlẹ ko ki i ṣe nkan ti a kan nilo ki Ọlọrun ba a le gbe wa ga nikan; a tun nilo rẹ lati le jẹ ki O ma ba a jẹ ki jabọ kuro ni ibi giga ti O fi wa si. Nitori eyi, fi ara rẹ sipo irẹlẹ niwaju rẹ. O ko si ni lailai ni idi kankan lati bẹru pe yoo re ọ jabọ.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Kò gbọdọ̀ jẹ́ fún ìgbà díẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ògún 10, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 15 Read More »

Ma rẹwẹsi | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ògún 03, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 14

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu ayọ ti o ga ni mo fi ki ọ kaabọ sinu oṣu Ogun 2025. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ṣe ọ yẹ pẹlu ohun gbogbo ti o nilo lati rin ni iṣẹgun lori gbogbo idojukọ aye rẹ ninu oṣu naa, ni orukọ Jesu. Amin.

Nigba ti Ọlọrun pe Joṣua lati gba iṣẹ lọwọ Mose ni didari awọn ọmọ Isiraẹli wọ inu Ilẹ Ileri, Ọlọrun sọ awọn ọrọ wọnyi fun un:

“Emi ko ha ti paṣẹ fun ọ bi? Jẹ alagbara ki o si mu aya le. Ma ṣe bẹru, ma si ṣe rẹwẹsi, nitori pe Oluwa a rẹ yoo wa pẹlu u rẹ ni ibikibi ti iwọ ba n lọ.” (Jóṣúà 1:9)

Ki ni idi ti Ọlọrun fi sọ fun ọkunrin yi lati ma bẹru tabi rẹwẹsi ṣugbọn lati jẹ alaragba ati ẹni ti aya rẹ le? Akọkọ, idi ni pe o di dandan ki o ba awọn asiko kan pade ti yoo fẹ dẹruba tabi kun ọkan rẹ pẹlu irẹwẹsi. Ti o ba si lọ bẹru tabi rẹwẹsi pẹrẹ, ko ni i le mu ete Ọlọrun fun aye rẹ ṣẹ.

Idi keji ti Ọlọrun fi sọ fun pe ki o ma bẹru tabi rẹwẹsi ni pe Oun funrarẹ yoo wa pẹlu rẹ lati daabo bo ati lati jẹ ki o rin ninu iṣẹgun nibikibi ti o ba lọ, bi o ti wu ki ibẹ lewu to. O wa ku sọwọ Joṣua lati gba ọrọ ti Ọlọrun ti sọ fun lati rin ninu iṣẹgun lori gbogbo idojukọ rẹ laye gbọ ati lati ṣiṣẹ le e lori. Ṣe o wa gba ileri Ọlọrun gbọ bi, ṣe o si tun ṣiṣẹ le lori? Bẹẹni. Idi si ni yi ti o ṣe ṣe aṣeyọri ni didari awọn ọmọ Isiraẹli lati jogun Ilẹ Ileri.

Nibakana, o di dandan ki awa naa ba awọn asiko pade laye ti yoo fẹ dẹruba wa tabi fi irẹwẹsi sinu ọkan wọ. A tilẹ le wa ni irufẹ awọn asiko naa lọwọlọwọ yi. Ṣugbọn bi o ti wu ki awọn asiko naa dẹruba wa to, Ọlọrun n sọ fun wa pe ki a ma bẹru wọn, ki a si ma jẹ ki wọn fi irẹwẹsi sinu ọkan wa. Ki ni idi? Idi ni pe yoo wa pẹlu wa nibikibi ti a ba lọ lati mojuto wa ati lati ri daju pe eṣu kọ pa aye wa run. Ti a ba si gba eyi gbọ, ti a si n ṣiṣẹ le lori, iṣẹgun yoo jẹ ti wa ni gbogbo ipo ti a ba ba ara wa laye.

Nitorina, bi o ti wu ki nkan ti o n dojukọ lọwọlọwọ yi ri, ma ṣe bẹru tabi rẹwẹsi. O le e dabi ẹni pe gbogbo ireti itusilẹ tabi iṣẹgun rẹ ni o ti bọ danu. Sibẹsibẹ, ma ṣe rẹwẹsi ni ṣiṣe ifẹ Ọlọrun. Dipo bẹẹ, tẹsiwaju lati ma a gbadura ati lati ma sọ ọrọ Ọlọrun ṣi awọn ipo ti o wa. Nipa bayi, oju ko ni ti ọ ṣugbọn iwọ yoo ni iriri iṣẹgun ti o ga.

Kí o ní oṣù Ògún 2025 alárinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ma rẹwẹsi | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ògún 03, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 14 Read More »