April 2026

Ṣùgbọ́n adẹ́tẹ̀ ni | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 26, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 52

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Pẹlu idunnu ti o ga ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o so oṣu Igbe ati Èbìbí 2026 papọ. Adura mi ni pe ki Ọlọrun, ni kiakia, ya aye rẹ ya ohun gbogbo ti o n mu akude ba didara rẹ ninu rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Mo gba adura yi fun ọ nitoripe a ma n ri awọn igba ti o jẹ wipe idi ti awọn nkan rere ti Ọlọrun n ṣe ninu aye awọn eniyan rẹ ko ki i fi ja mọ nkankan ni pe awọn nkan kan ninu aye wọn n mu akude ba wọn. Ti a ko ba si mojuto awọn nkan wọnyi, ko si nkan rere kankan ti O le ṣe fun wọn ti yoo fun wọn ni itẹlọrun ati isinmi ni aye.

Fun apẹrẹ, a ko eyi sinu bibeli nipa ọkunrin kan ti a n pe ni Naamani:

“NJẸ Naamani, olori-ogun ọba Siria, jẹ enia nla niwaju oluwa rẹ̀, ati ọlọla, nitori nipa rẹ̀ ni Oluwa ti fi iṣẹgun fun Siria: on si jẹ alagbara akọni ọkunrin ṣugbọn adẹtẹ̀ ni.” (2 Àwọn Ọba 5:1)

Ta ni o mu Naamani di ẹni nla, bi a ti ṣe ri ninu ẹsẹ bibeli yi? Ọlọrun ni. Oun ni O sọ di ẹni ti gbogbo eniyan ni orilẹ-ede rẹ, pẹlupẹlu ọba rẹ, ka si ẹni pataki ati ẹni-ọwọ. Ṣugbọn pẹlu gbogbo awọn nkan ti Ọlọrun ṣe fun-un wọnyi, ko ki ṣe ẹnikan ti inu rẹ dun, ti o si tun ni balẹ ọkan tan yanyan. Ki ni idi? Adẹtẹ ni. Eyi jasi pe, o jẹ ẹnikan ti wọn yo pada ya sọtọ kuro lọdọ gbogbo awọn ti o fẹran rẹ, ti yoo si wa ma a da gbe. Aijẹbẹ, wọn le ko ẹtẹ rẹ.

Ki wa ni titobi rẹ yoo ja mọ? Ki ni ọrọ rẹ yoo ja mọ? Ki si ni gbogbo awọn iṣẹ akikanju ti Ọlọrun ti tipasẹ rẹ ṣe yoo ja mọ? Gbogbo awọn nkan wọnyi ni ẹtẹ rẹ yoo pada sọ di asan. Ẹtẹ rẹ ko ni jẹ ki o jẹ igbadun wọn lẹkunrẹrẹ tabi fun igba pipẹ. Ero lori eyi nikan gan an ro lati sọ di onibinujẹ ẹniyan.

Awa dupẹ pe Ọlọrun lo ọdọmọbirin ẹru kan ti a mu wa si ile rẹ lati ilẹ Isiraẹli lati ran an lọwọ lati ri iwosan rẹ gba. Ọdọmọbinrin yi sọ fun un nipa Wolii Eliṣa ati bi Ọlọrun ṣe le lo o lati wo ẹtẹ rẹ san. Nigba ti o si lọ si ọdọ eniyan Ọlọrun yi, a wo ẹtẹ rẹ san nitootọ. Nitorina, lati ọjọ naa lọ, o bẹrẹ si ni sin Ọlọrun, o si tun bẹrẹ si ni jẹ igbadun ohun rere gbogbo ti Ọlọrun ti ṣe fun pẹlu itẹlọrun ati laisi ibẹru.

Wayi o, Ọlọrun kanna ti O mojuto ẹtẹ Naamani le mojuto ohunkohun ti o n di ọ lọwọ lati jẹ igbadun didara rẹ ninu aye rẹ lẹkunrẹrẹ. Nkan ti o kan nilo lati ṣe ni ki o ke pe e fun iranlọwọ. Bi o si ti n ṣe eyi, gbogbo ‘Ṣugbọn’ ti o n sọ didara rẹ di alainitunmọ ninu aye rẹ ni a o mojuto. Iwọ yoo si wa bẹrẹ si ni jẹ igbadun awọn ibukun rẹ pẹlu itẹlọrun.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ṣùgbọ́n adẹ́tẹ̀ ni | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 26, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 52 Read More »

Ẹ̀ṣẹ̀ ÉlìLáti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 19, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 51

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Igbe 2026. Mo gbadura pe ki Ọlọrun ma jẹ ki o lugbadi idajọ rẹ lori ọkankan ninu awọn ti o wa ninu aye rẹ tabi ni ayika rẹ. Amin.

Wayi o, mo gba adura yi fun ọ nitoripe ko ki i ṣe gbogbo igba ti awọn eniyan ba ni iriri idajọ Ọlọrun naa ni o jẹ nitoripe awọn funrawọn buru ni. Igba miran wa ti awọn eniyan a ma a ni iriri idajọ Ọlọrun nitoripe wọn kuna lati lo aṣẹ wọn lati ṣe idajọ awọn ti o wa ni abẹ iṣakoso wọn. Fun apẹrẹ, Ọlọrun sọ eyi fun Samuẹli nipa alufa Eli:

“Nitoriti emi ti wi fun u pe, emi o san ẹsan fun ile Eli titi lai, nitori iwa buburu ti on mọ̀, nitori awọn ọmọ rẹ̀ ti sọ ara wọn di ẹni ẹgàn, on kò si da wọn lẹkun.” (1 Sámúẹ́lì 3:13)

Ki ni idi ti Ọlọrun ṣẹ fẹ ṣe idajọ idile Eli? Ṣe nitoripe ọkunrin naa buru ni? O ti o! Abi ṣe nitoripe awọn ọmọ rẹ kan buru ni? O ti o! Idi ti Ọlọrun fi fẹ ṣe idajọ idile rẹ ni pe o kuna lati mu awọn ọmọ rẹ so, bi o tilẹ jẹ wipe o mọ nipa ẹṣẹ wọn daadaa.

Ti Eli ko ba mọ nipa ẹṣẹ awọn ọmọ rẹ ni, Ọlọrun ko ma ba ti da lẹbi nitori wọn. Lafikun, ti Eli ko ba wa ni ipo ẹni ti o le da awọn ọmọ rẹ lẹkun ni, ki wọn ma ba a le ma ṣẹ si Ọlọrun bi o ti ṣe wu wọn, ko ba ma ti da a lẹbi nitori wọn. Ṣugbọn yatọ si pe o mọ nipa ẹsẹ wọn, o tun wa ni ipo lati da wọn lẹjọ ati lẹkun. Sibẹsibẹ, o kuna lati ṣe eyi. Nitorina, Ọlọrun sọ fun pe Oun yoo ṣe idajọ idile rẹ fun ẹṣẹ awọn ọmọkunrin naa.

Njẹ ki wa ni idi ti Ọlọrun fi kọkọ sọ fun un nipa idajọ rẹ ti o n bọ ṣaju asiko idajọ naa? Idi ni ki o ba a le ṣe ohun ti o tọ pẹlu ikanju. Ṣe o wa ṣe ohun ti o tọ? Rara o, ko ṣe e. Dipo eyi, esi ti o fọ ni pe aaye pọ fun Ọlọrun lati ṣe ohun yowu ti o ba tọ loju rẹ lori ọrọ naa. Eyi jasi pe, ni titiẹ, ko ṣetan lati tun yọ ara rẹ lẹnu lori nkan ti awọn ọmọkunrin rẹ n ṣe mọ. (Wo: 1Sámúẹ́lì 3:18)

Ki wa ni eyi n kọ wa, ki a ma fọrọgun? Oun naa ni pe ti Ọlọrun ba fi awọn eniyan si abẹ iṣakoso wa, ko reti pe ki a fi aye gba wọn lati ma a ṣe bi o ba ṣe wu wọn. Dipo eyi, nkan ti O n reti ni pe ki a ma a lo aṣẹ wa lati fi wọn si aaye wọn, ti wọn ba n ṣe radarada. Aijẹbẹ, nṣe ni a o ma da ẹṣẹ Eli. Ti eyi ba si ri bẹ, igbakugba ti Ọlọrun ba da si ọrọ naa lati ṣe idajọ iwa ika ti a kọ lati ṣe idajọ rẹ, o di dandan ki awa naa kopa ninu idajọ naa, ayafi ti a ba ṣaanu fun wa. Ta wa ni o mọ ọna ti Ọlọrun yoo gba ṣe idajọ?

Nitorina, ma ṣe da bi Eli ti o kọ lati ṣiṣẹ lori ikilọ Ọlọrun lati ṣe idajọ awọn ọmọ rẹ nitoripe radarada wọn su u. Dipo eyi, nṣe ni ki o bẹrẹ si ni lo aṣẹ rẹ lati fi gbogbo nkan si aaye wọn nibikibi ti o ba ti ni aṣẹ lati ṣe bẹ ẹ. Nipa bayi, iwọ yoo le pa ara rẹ mọ lati ma kopa ninu idajọ awọn alaigbọran.

Siwaju si, ma ṣe jẹ ki inu bi ọ nigba ti awọn ti o ni aṣẹ lori rẹ ko ba fi aaye gba ọ lati ma ṣe radarada labẹ isakoso wọn. Idi si ni pe ifẹ Ọlọrun ni wọn nṣe. Yatọ si iyẹn, nipa bi wọn ko ṣe fi aaye gba ọ lati ma ṣiwawu labẹ isakoso wọn, nṣe ni wọn n pa ọ mọ kuro labẹ idajọ Ọlọrun. Nitorina, nṣe ni o yẹ ki o ma dupẹ lọwọ wọn fun bi wọn ṣe jẹ adari ti o mọ ojuṣe wọn. Aijẹbẹ, o le ṣe ara rẹ leṣe nipasẹ idajọ Ọlọrun, ti o ba kọ lati gba ibawi. Mo gbadura pe iru eyi ko ni jẹ ipin rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ẹ̀ṣẹ̀ ÉlìLáti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 19, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 51 Read More »

Ayé ò dọ́gba | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 12, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 50

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodwiọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Adura mi ni pe ki Ọlọrun lo gbogbo ipokipo ti o le ba aye rẹ, bi o ti wu ki o buro loju to, lati mu ete rere rẹ ṣẹ ninu aye rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, ki ni idi ti mo fi gba adura yi fun ọ? Idi ni pe mo mọ pe aye ko dọgba. Wo, fun apẹrẹ, nkan ti Solomọni sọ nipa eyi:

“Mo pada, mo si ri labẹ õrùn, pe ire-ije kì iṣe ti ẹniti o yara, bẹ̃li ogun kì iṣe ti alagbara, bẹ̃li onjẹ kì iṣe ti ọlọgbọ́n, bẹ̃li ọrọ̀ kì iṣe ti ẹni oye, bẹ̃li ojurere kì iṣe ti ọlọgbọ́n-inu; ṣugbọn ìgba ati eṣe nṣe si gbogbo wọn.” (Oníwàásù 9:11)

Njẹ o ri bayẹn? Aye ko kan ni funralara rẹ ṣiṣẹ fun ire ẹnikẹni, bi o ti wu ki awọn amuyẹ ẹni naa ga to. Idi ni yi ti a fi ni ọpọ eniyan ti wọn ni awọn amuyẹ ti o ga, ti wọn si tun n gbe igbe aye ailojutu. Awọn amuyẹ wcn ti o yẹ ki o gbe wọn leke laye ko wulo fun wọn lọna ti o nitunmọ kankan. Awọn amuyẹ wọnyi tilẹ tun le ma a ṣiṣẹ lodi si wọn.

Ki ni idi? Idi ni pe aye ko dọgba. Aye ko kan ni fun ọ ni aṣeyọri tabi ibalẹ-ọkan nitori awọn amuyẹ, ibaṣepọ tabi iṣẹ karakara rẹ. Nṣe ni o ni lati wa ni ibi ti o tọ, ni asiko ti ọ tọ, ki o si ma ṣe ohun ti tọ. Aijẹbẹ, gbogbo amuyẹ, ọgbọn, ẹkọ ati anfaani ti o ni le pada ja si pabo.

Bawo wa ni o ṣe le fi ara rẹ si ibi ti o tọ, ni asiko ti o tọ, ki o si tun ma ṣe ohun ti o tọ pẹlu nibẹ? Nipa fifa ara rẹ le ẹni ti o ni aye lọwọ ni. Ti o ba fa ara rẹ le ẹni ti o ni aye lọwọ, O le kọ ni ohun ti o dara julọ fun ọ, ki O si tun dari rẹ ni ọna ti o yẹ ki o tọ. (Wo: Àìsáyà 48:17)

Amọ ṣe iwọ yoo ṣe eyi bi? Ṣe iwọ yoo fa aye rẹ le Ọlọrun, ẹni ti o ni aye, lọwọ, ki O ba a le dari rẹ si ọna ti o yẹ ki o tọ laye, ki O si fi idi rẹ mulẹ ninu ododo, alaafia ati iṣerere? Nitorina, bi o tilẹ jẹ wipe aye ko ṣe ọ daada, ko ni le da ọ duro lati jẹ ẹni ti o yẹ ki o jẹ lorilẹ aye.

Ranti pe bi o tilẹ jẹ wipe aye ko ṣe daada si Josefu, o si papa jẹ ẹni to yẹ ki o jẹ laye. Idi si ni pe o fa ara rẹ le Ọlọrun lọwọ. Nitorina, ma ṣaroye mọ pe aye ko ṣe ọ daada. Nṣe ni ko mura lati dojukọ aye lọna yowu ti o ba gba yọ si ọ, irufẹ ọda ti o le fi kun ara rẹ. Bẹẹni, o nilo lati ṣẹgun ninu aye, bi o ti wu ki nkan ma ṣe deede si ọ to. Ọna kan ṣoṣo lati ṣe eyi, bi mo ti ṣe sọ tẹlẹ, ni ki o fa ara rẹ le Ọlọrun lọwọ. Nitorina, fa ara rẹ lọwọ. Iwọ yoo si pada duro gẹgẹ bi aṣẹgun lẹyin-ọ-rẹyin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ayé ò dọ́gba | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 12, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 50 Read More »

Àjọyọ̀ Àjíìnde | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 05, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 49

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kiristi Oluwa wa. Pẹlu idunnu ni mo ki ọ kaabọ sinu oṣu miran ninu ọdun yi, iyẹn oṣu Igbe 2026. Adura mi ni pe ki Ọlọrun ṣe ohun gbogbo ti o ni ṣe pẹlu rẹ ni aṣepe ninu oṣu naa, ki O si tun fun ọ ni isinmi ni gbogbo ọna. Amin.

Gẹgẹ bi a ti ṣe mọ, eni jẹ ọjọ ti pupọ-julọ ninu awọn Kirisitiẹni kaakiri agbaye n ṣe ajọyọ ajiinde Jesu Kirisiti Oluwa wa. Bi o tilẹ wa jẹ wipe a ri awọn Kirisitiẹni ti ko ri idi fun irufẹ ajọyọ yi, paapaa julọ niwọn igba ti Jesu Oluwa wa ko pa a laṣẹ fun wa lati ṣe bẹẹ, a ko le sọ wipe nkan ti ko dara ni. Nkan ti mo n sọ ni pe ko si nkan ti o buru ninu ki a ya ọjọ kan sọtọ lati ṣe ajọyọ ajiinde, ki a si sọ fun gbogbo agbaye nkan ti Jesu ṣe fun igbala ọmọniyan.

Amọ ṣa o, ni ṣiṣe ajọyọ ajiinde, a ko tun wa gbọdọ fi ara wa fun ṣiṣe awọn nkan ti Oluwa wa wa lati gba wọn lọwọ wa. Eyi jasi pe, ajọyọ ajiinde wa ko gbọdọ yọri si imuti-para, apejẹ iṣọnu tabi iṣekuṣe. Dipo eyi, nṣe ni o yẹ ki o kọkọ jẹ ajọyọ fifi ọpẹ fun Ọlọrun fun bi O ti ṣaanu fun wa, ti O si ran Jesu lati ra wa pada.

Ekeji, ajọyọ wa gbọdọ jẹ eyi ti yoo tọ wa lati ran ara wa leti nkan ti ajiinde Jesu Kiristi yanju fun wa. Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, nitori ajiinde rẹ ni a ṣe duro siwaju Ọlọrun lọwọlọwọ yi gẹgẹ bi ẹni idalare. Lafikun, nitori ajiinde rẹ ni a ṣe jẹ ẹda tuntun ati olododo eniyan niwaju rẹ lọwọlọwọ yi. Yatọ si iyẹn, nitori ajiinde rẹ ni a ṣe ni agbara lori Satani, ẹṣẹ ati aye yi lọwọlọwọ yi. (Wo: Róòmù 5:25; 2Kọ́ríntì 5:17-21)

Nitorina, nkan ti yoo jẹ ki ajọyọ ajiinde wa ni itunmọ ni ki a ma rin pẹlu afiyesi awọn nkan wọnyi. Ti a ko ba ma a rin pẹlu aifyesi wọn, ajọyọ ajiinde wa ko ni itunmọ. Nṣe ni a o kan ma fi han pe asan ni ohun ti O ṣe fun wa.

Wayi o, adura mi ni pe ohun ti Jesu ṣe fun iwọ ati emi nipasẹ iku, isinku ati ajiinde rẹ ko ni lailai ja si asan. Ṣugbọn awa naa gbọdọ ma a fi igba gbogbo ṣe asaro lori nkan ti O ṣe fun wa, ki a ba a le ma a fi ojoojumọ ṣe amulo rẹ lati jẹ ẹni ti Ọlọrun fẹ ki a jẹ. Mo ki ọ kaabọ lẹẹkansi sinu oṣu tuntun yi. Mo si tun gbadura pe ki o jẹ igbadun ere ajiinde Jesu Oluwa wa lẹkunrẹrẹ ninu aye rẹ ninu oṣu naa. Amin.

A ku Ajiinde.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Àjọyọ̀ Àjíìnde | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 05, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 49 Read More »