May 2026

Ọdún ìbádàpọ̀ míràn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbì 17, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 03

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ ni ilọpo-ilọpo lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Pẹlu idunnu ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu yi, iyẹn oṣu Ebibi 2026. Adura mi ni pe ki Ọlọrun ṣe ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu aye rẹ ninu ọsẹ naa ni aṣepe, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe mọ, a n ṣe ayẹyẹ ọdun kẹrinla ti a ti n pade ninu ilu yi gẹgẹ bi ijọ loni. Ni akọkọ, mo dupẹ lọwọ Ọlọrun fun ohun gbogbo ti O ti jẹ si wa, ti O ti ṣe fun wa, ti O ti ṣe ni aarin wa ati ti O ti ṣe nipasẹ wa ninu awọn ọdun wọnyi. Ki iyin jẹ ti orukọ rẹ ti o logo titi lailai.

Lafikun, mo tun fẹ dupẹ lọwọ gbogbo awa ti a ri ara wa gẹgẹ bi ojulowo ọmọ ijọ yi fun fifi aye gba Ọlọrun lati fi ọwọ tọ ọkan wa lati darapọ mọ ara wa ninu ibadapọ pẹlu rẹ, Mo si tun dupẹ lọwọ wa fun fifi aaye gba a lati tọ wa lati kọpa lọna ti o peye ninu ohun gbogbo ti o n mu ijọ naa tẹsiwaju. Adura ni pe ki Oluwa dardara tẹsiwaju lati ma a ṣiṣẹ ninu wa titi gbogbo ero rẹ si wa ni rere yoo fi wa si imuṣẹ ninu aye wa, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, bi a ti ṣe n bẹrẹ ọdun ibadapọ miran, mo fẹ gba wa niyanju lati fi ara wa jin siwaju si fun ọrọ rẹ, fun adura gbigba, fun ibadapọ pẹlu ara wa ati fun jijẹ ẹri didara Ọlọrun si wa fun awọn ti o wa ni ayika wa. Ki ni idi? Idi ni pe awọn nkan wọnyi ni awọn eniyan mimọ igbaani fi ara wọn jin fun. Nipa bi wọn si ṣe fi ara wọn jin fun awọn nkan wọnyi, Ọlọrun ri aaye lati gbe gbogbo wọn ro lati jẹ irinṣẹ ti o ga ni ọwọ rẹ ni yiyi aye ọpọ kaakiri agbaye pada. (Wo: Ìṣe Àpọ́sítélì 2:42-42 & 8;41)

Nitorina, niwọn igba ti awa naa fẹ ki Ọlọrun gbe ẹnikọọkan wa ro lati wulo gidigidi fun un ni fifi ọwọ kan aye ọpọ ni ayika wa, a wa gbọdọ fi ara wa jin fun ọrọ rẹ, adura gbigba, ibadapọ pẹlu ara wa ati ẹri jijẹ fun awọn ti o wa ni ayika wa ju tatẹyin wa lọ. Eyi, lotitọ, le ma rọrun, nitoripe ṣiṣe awọn nkan ti o n gbe eniyan ro ko ki i fi igba gbogbo wa pẹlu irọrun. Ṣugbọn ṣiṣe eyi yoo lere lori lọna ti o ga fun wa ati fun awọn ti o wa ni ayika wa.

Mo ki ọ kaabọ lẹkaansi sinu ọdun ibadapọ miran ninu oore-ọfẹ Ọlọrun. Mo si fẹ ki o foju sọna fun iriri didara Ọlọrun ti o ga ju tatẹyinwa lọ ninu aye rẹ ati ninu ijọ wa, bi gbogbo wa ṣe n fi ara wa jin siwaju si fun idari Ẹmi rẹ.

Kí Ọlọ́run kí ó bùkún fún ọ.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ọdún ìbádàpọ̀ míràn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbì 17, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 03 Read More »

Ìkà àti ọ̀dájú ènìyàn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbì 10, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 02

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Èbìbí 2026. Adura mi ni pe ki Ọlọrun pa ọ mọ ninu ọsẹ yi ati ni gbogbo eyi ti o ku ninu ọdun yi kuro lọwọ awọn ika ati ọdaju eniyan nibikibi ti o ba ya si, ni orukọ Jesu. Amin.

Pọọlu, ninu lẹta rẹ keji si awọn ara Tẹsalonika, sọ eyi:

“Ati ki a le gbà wa kuro lọwọ awọn eniyan buburu ati awọn ika eniyan: nitori pe kii ṣe gbogbo eniyan ni o gbagbọ́.” (2 Tẹsalóníkà 3:2)

Ki ni nkan ti a ni ki a gbadura fun? A ni ki a gbadura pe ki Ọlọrun gba wa lọwọ awọn ika ati ọdaju eniyan. Eniyan ja si pe a ni ninu aye yi awọn ika ati ọdaju eniyan. Irufẹ awọn wọnyi a ma a ṣetan lati gbe igbesẹ-ki-gbesẹ lati han ẹnikẹni ti o ba ṣẹ wọn leemọ, bi o tilẹ jẹ wipe ko si ẹṣẹ kankan ninu ọrọ yowu ti o wa nilẹ. Lafikun, irufẹ awọn wọnyi ko ki i ṣaba gbẹbẹ. Ti wọn ba ti pinnu lati ṣe ẹnikan ni ewu, o di dandan ki wọn ṣe bẹẹ gẹgẹ, bi eyi yoo tilẹ gba gbogbo asiko aye wọn tabi gbogbo owo wọn. Nitorina, ayafi ti Ọlọrun ba pa wa mọ kuro lọwọ wọn, a ko le bọ lọwọ iwa buburu wọn.

Fun apẹrẹ, ọkunrin kan ti a n pe ni Hamani ṣetan lati pa Mọdẹkai ati gbogbo awọn Juu ti o wa labẹ ijọba Ọba Ahasiwerusi nitoripe Mọdẹkai ri fin. Ṣugbọn ẹnikan ṣoṣo ni Mọdẹkai. Ki wa lo de ti Hamani fi fẹ pa gbogbo awọn Juu nitori tirẹ? Idi ni pe ika ati ọdaju eniyan ni. Ti Mọdẹkai ati awọn eniyan rẹ ko ba si lọ gbadura si Ọlọrun pe ki O da si ọrọ naa ni, ọpọlọpọ wọn ni ko ba padanu ẹmi wọn nitori iwa buburu Hamani. (Wo: Ésítà 3-9)

Ti Ọba Hẹrọdu nkọ? Ọkunrin yi ran awọn jagun-jagun rẹ lati lọ pa gbogbo awọn ọmọ wẹwẹ ọdun meji ati awọn ti ko to bẹẹ ti o wa ni Betilẹhẹmu nitoripe o ṣa fẹ pa Jesu nigba ti o wa ni ọmọ irinsẹ. Ki ni idi? Ko fẹ ki o dagba di ọba awọn Juu. Niwọn igba ti ko si wa mọ ọmọde naa ti a n pe ni Jesu, o ba kuku pinnu lati pa gbogbo awọn ọmọ wẹwẹ ti o wa ni Bẹtilẹhẹmu, nibi ti a ti bi Jesu, ti wa ni iwọn ọjọ ori rẹ. Ti Ọlọrun ko ba wa da si ọrọ naa ni, a ko ba ti pa Jesu ki o to di pe yoo tilẹ ni anfaani lati ṣe iṣẹ ti Ọlọrun ran wa si aye lati ṣe. (Wo: Mátíù 2:1-18)

Ki ni koko ọrọ mi? Ohun naa ni pe awọn ika ati ọdaju eniyan bi Hamani ati Hẹrọdu si wa digbi ninu aye yi ati ni ayika wa. Satani si le lo wọn nigbakugba ati fun idi-ki-di lati kọlu wa. Ṣugbọn Ọlọrun le pa wa mọ kuro lọwọ wọn. Awa na, ẹwẹ, ko gbọdọ duro de igba ti eyi yowu ninu wọn yoo ma halẹ mọ wa ki a to kọ lati ma gbadura fun aabo Ọlọrun kuro lọwọ wọ. Aijẹbẹ, wọn le ti jẹ wa niya tan ki o to di pe a o ri aaye lati gbadura.

Nitorina, kọ bi a ṣe n gbadura lojoojumọ pe ki Ọlọrun ma pa ati iwọ ati ohun gbogbo ti o jẹ tirẹ mọ ni gbogbo igba kuro lọwọ awọn ika ati ọdaju eniyan ti o wa layika rẹ. Yoo si ri bẹ ẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ìkà àti ọ̀dájú ènìyàn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbì 10, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 02 Read More »

Má mú Ọlọ̀run banújẹ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbì 03, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 01

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Pẹlu idunnu ti o ga ni mo ki ọ kaabọ sinu oṣu kaarun ọdun yi, iyẹn oṣu Èbìbí 2026. Adura mi ni pe ki Ọlọrun ma a fi igba gbogbo pa ọ mọ, ki o ma ba a ṣe ohunkohun ti yoo ba a ninujẹ, ti yoo si jẹ ki O yi ọkan rẹ pada lori mumi awọn eto rẹ fun aye rẹ ṣẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, mo gba adura yi fun ọ nitoripe o ṣeeṣe ki a mu inu Ọlọrun bajẹ. Bẹẹni, o ṣeeṣe ki a ba a ninujẹ nipa bi a ṣe n gbe aye wa ati nipa iha ti a n kọ si ọrọ rẹ. Idi si ni pe O fẹran wa. Kiki awọn ti a ba fẹran, ti a si n kẹ, ni wọn le ba wa ninujẹ tabi mu ọkan wa poruru. Awọn ti a ko ba fẹran ko le ba wa ninujẹ, bi o ti wu ki iwuwasi wọn si wa buru to. Ki a tilẹ sọ otitọ, ọpọ ninu wa ni ko tilẹ ni fẹ fi aye gba ẹnikẹni ti a ko fẹran lati ṣe ohunkohun ti yoo mu wa karisọ.

Ṣugbọn ti ẹnikan ti a fẹran, ti o si tobi lọwọ wa, ba bẹrẹ si ni wu iwa aikanisi si wa, inu wa ko ni dun rara. Ti irufẹ ẹni bẹ ẹ ba si tun wa tẹsiwaju lati ma mu inu wa bajẹ lọna yi, a le yi ọkan wa pada lori rẹ, ki a si mu ifẹ ti a ni si wọn kuro lọkan wa. Lẹyin eyi, wọn ko tun ni le jẹ igbadun ibaṣepọ wọn pẹlu wa bi wọn ti ṣe ma n jẹ tẹlẹ mọ.

Nibakanna, nitoripe Ọlọrun fẹran wa, a le mu inu rẹ bajẹ. Ti a ba si wa fi mimu inu rẹ bajẹ ṣe aṣa, asiko naa le de ninu eyi ti yoo yi ọkan rẹ pada lori wa ati lori eto rẹ fun wa. Bawo wa ni a ko ṣe ni fi aye wa ṣofo tabi pa aye wa run, ti eyi ba lọ waye?

Fun apẹrẹ, a sọ eyi nipa idi ti Ọlọrun fi yọ Ọba Sọọlu kuro ni ipo rẹ gẹgẹ bi ọba lori orilẹ-ede Isiraẹli:

“Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ Samueli wá wipe, Emi kãnu gidigidi ti emi fi Saulu jọba: nitoriti o ti yipada lẹhin mi, kò si mu ọ̀rọ mi ṣẹ. O si ba Samueli ninu jẹ gidigidi; on si kepe Oluwa ni gbogbo oru na.” (1 Sámúẹ́lì 15:10-11)

Njẹ o ri bayẹn? Inu Ọlọrun bajẹ nitoripe O fi Sọọlu ṣe ọba lori Isiraẹli. Ki si ni idi? Idi ni pe ọkunrin naa sọ di aṣa lati ma tapa si aṣẹ rẹ. Nkan ti o tun wa buru ju iyẹn lọ ni pe ko tilẹ ni ẹmi ironupiwada rara. O ni i lara lati fi tọkan-tọkan roninupiwada ti a ba ba a wi tabi sọ pe ki o tun iwa rẹ ṣe. Nitorina, Ọlọrun yi ọkan rẹ pada lori ọrọ rẹ, O si fi ẹlomiran rọpo rẹ.

Njẹ Sọọlu wa kaanu lori ọrọ yi bi, nigba ti Ọlọrun yi ọkan rẹ pada lori ọrọ rẹ, ki O si wa oju rẹ fun aanu? Rara o, ko ṣe bẹ ẹ. Nṣe ni o kan n ba iṣe rẹ lọ gẹgẹ bi ọba, bi igba ti ko si nkankan ti o ṣẹlẹ. Nitorina, o pada pa aye ara rẹ fun, o si sọ ohun rere yowu ti o ṣe fun orilẹ-ede Isiraẹli gẹgẹ bi ọba di asan.

Amọ ṣa o, bi a ti ṣe ri ninu akọsilẹ naa, Samuẹli ti ko ki i ṣe oun ni a rọ loye ko dẹkun lati ma kẹdun niwaju Ọlọrun fun ọkunrin yi. Lotitọ, nigba ti o tilẹ de ikorita kan, Ọlọrun ni lati sọ fun pe ki o ye kẹdun lori ọrọ Sọọlu mọ, ki o si lọ ta ororo si elomiran lori rọpo rẹ (1 Sámúẹ́lì 16:1). Ki wa lo fa ti o fi n kẹdun fun Sọọlu bi iyẹn? Idi ni pe o mọ babara ki a mu inu Ọlọrun bajẹ ati pataki ki a ronupiwada lotitọ ti a ba ti ṣe bẹ ẹ. Aijẹbẹ, a le pada fi aye wa ati oore-ọfẹ yowu ti a le ti ri gba lọwọ Ọlọrun ṣofo.

Eyi si wa ni idi ti a fi kilọ fun awa naa ninu Iwe Mimọ ni ọna yi:

“Ẹ má si ṣe mu Ẹmí Mimọ́ Ọlọrun binu, ẹniti a fi ṣe èdidi nyin dè ọjọ idande.” (Éfésù 4:30)

Njẹ o ri bayẹn? A gbọdọ ṣo ara wa ki a ma ba a fi ara wa jin fun ṣiṣe ohunkohun ti o le ba Ẹmi Ọlọrun ti O n gbe inu wa ninujẹ. Ti a ba si ti n ba ninu jẹ ni ọna kankan, nṣe ni ki a ronupiwada, ki a si wa oju rẹ fun aforiji ni kiakia. Aijẹbẹ, gẹgẹ bi Ọba Sọọlu, awa naa le pada fi gbogbo ifẹ ati oore-ọfẹ ti O ti tu si ori wa lẹkunrẹrẹ ṣofo. Njẹ ki eyi ma jẹ ipin wa, ni orukọ Jesu. Amin.

Kí o ní oṣù Èbìbí 2026 alárinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Má mú Ọlọ̀run banújẹ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbì 03, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 01 Read More »