August 2026

Ajogún Ọlọ́run | Lati ọwọ: Omotola Dunsin Babarinde | Ọjọ: Ogun 30, 2026 | Atẹlera: Látorí tábìli Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 18

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o so oṣu Ògún ati Òwewè 2026 mọ ara wọn. Adura mi ni pe ki Ọlọrun kun ọ pẹlu oye ti o peye lori ipo rẹ ninu ijọba rẹ, ki o ma ba a gbẹyin ninu nini iriri didara rẹ ni ọna kankan. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ipo ti gbogbo awa ti o gbagbọ ninu Jesu Kirisiti wa ninu ijọba Ọlọrun jẹ ipo ọmọ. O si ṣe pataki ki a ma a fi igba gbogbo fi eyi sọkan, ki a ba a le ma gbe ni ibamu pẹlu rẹ. Wo nkan ti Pọọlu sọ lori rẹ:

“Ẹmí tikararẹ̀ li o mba ẹmí wa jẹrí pe, ọmọ Ọlọrun li awa iṣe: Bi awa ba si jẹ ọmọ, njẹ ajogun li awa, ajogun Ọlọrun, ati ajumọ-jogun pẹlu Kristi; biobaṣepe awa bá a jìya, ki a si le ṣe wa logo pẹlu rẹ̀.” (Róòmù 8:16-17)

Ṣe o ri bayẹn? Ọmọ Ọlọrun ni a jẹ. Niwọn igba ti a si jẹ ọmọ Ọlọrun, ajogun rẹ ni a tun jẹ pẹlu. Ṣugbọn ki a to le ni oye ti o peye lori nkan ti o tunmọsi lati jẹ ajogun Ọlọrun, a kọkọ gbọdọ ni oye pe ọmọ rẹ ni a jẹ ati wipe inu ẹbi rẹ ni a wa. Jòhánù 1:12 sọ wipe, “Ṣugbọn iye awọn ti o gbà a, awọn li o fi agbara fun lati di ọmọ Ọlọrun, ani awọn na ti o gbà orukọ rẹ̀ gbọ́.”

Wayi o, jijẹ ọmọ Ọlọrun ko ni nkankan ṣe pẹlu ọrọ wa, ilu-abinibi wa, ẹkọ wa tabi ipo wa lawujọ. O ni i ṣe pẹlu igbagbọ ninu Jesu Kirisiti. Nitorina, ti o ba ni igbagbọ ninu Jesu Kirisiti Oluwa, ọmọ Ọlọrun ni o jẹ (Gàlátíà 3:26). Ti o ba si wa jẹ ọmọ Ọlọrun, a jẹ wipe ajogun rẹ ni o jẹ pẹlu.

Ta wa ni ajogun? Ajogun ni ẹni ti o ni lẹtọ labẹ ofin lati gba ogun kan tabi omiran. Roomu 8:17 sọ fun wa pe niwọn igba ti a ba jẹ ọmọ Ọlọrun, ajogun rẹ ati ajumọ-jogun pẹlu Kiristi ni a jẹ. Eyi jasi pe ibaṣepọ wa pẹlu Ọlọrun ko ja si asan. Ogun wa ti o soro mọ jijẹ tirẹ.

Ni Gàlátíà 4:17, Pọọlu sọ fun wa pe, “Nitorina iwọ kì iṣe ẹrú mọ́, bikoṣe ọmọ; ati bi iwọ ba iṣe ọmọ, njẹ iwọ di arole Ọlọrun nipasẹ Kristi.” Ki wa ni ogun wa? Akọkọ, a ni lati mọ wipe ogun wa kọja nkan ti aye yi. 1 Pétérù 1:4 sapejuwe ogun wa lọna yi: “Ogún aidibajẹ, ati ailabawọn, ati eyi ti kì iṣá. Bi a si tun ṣe ri ninu bibeli, a ti jogun awọn nkan wọnyi lati ọwọ Ọlọrun:

• Iye ainipẹkun – Jòhánù 3:16
• Idurotini Ẹmi Mimọ – Éfésù 1:13-14
• Ijọba Ọlọrun – Jèmíísì 2:5
• Irẹpọ pẹlu Ọlọrun – Róòmù 5:1
• Ireti ogo ainipẹkun – 1 Pétérù 1:3-4

Wayi o, mimọ pe a jẹ ajogun Ọlọrun yẹ ki o yi bi a ṣe n gbe aye pada. Ajogun tabi arole gbọdọ ma a gbe ile aye bi Baba rẹ ni. Nitorina, a gbọdọ ma a ṣoju Baba wa daradara. Ọrọ wa, iwa wa, ibaṣepọ wa ati iṣesi wa gbọdọ fi han pe ti Ọlọrun ti a n ṣe, lalai fi ti ipo ti a wa ṣe. Nitorina, ma jẹ ki ipo ti o ba ara rẹ lasiko yi jẹ ki o gbagbe ẹni ti o jẹ.

Siwaju si, pe a jẹ ajogun Ọlọrun ko tunmọ si pe a ko ni ba iṣoro pade. Róòmù 8:17 naa sọ fun wa pe ara nkan ti o sorọ mọ jijẹ ajumọjogun pẹlu Kirisiti ni ki a pin ninu ijiya rẹ ki a to di alabapin ninu ogo rẹ. Amọ ṣa o, awọn ijiya ti a n dojukọ lọwọlọwọ ko le fagile ogun wa ti a fipamọ de wa. Roomu 8:18 sọ pe, “Nitori mo ṣíro rẹ̀ pe, ìya igba isisiyi kò yẹ lati fi ṣe akawe ogo ti a o fihàn ninu wa.”

Nitorina, bi o tilẹ jẹ wipe o ko ni ohun gbogbo ti o wu ọ lati ni loni, ti o ba jẹ ti Kirisiti, o ni ogun ti ko le parun. Eyi si yẹ ki o fun ọ ni iwuri lati ma a fi ojoojumọ gbe aye rẹ lati bu ọla fun Ọlọrun. Mo si gbadura pe ki o gba okun lati ṣe bẹẹ gẹgẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ajogún Ọlọ́run | Lati ọwọ: Omotola Dunsin Babarinde | Ọjọ: Ogun 30, 2026 | Atẹlera: Látorí tábìli Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 18 Read More »

Ìdì tí wọn kò kí fí ṣiṣẹ́ lórí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run | Lati ọwọ: J.O. Lawal | Ọjọ: Ogun 23, 2026 | Atẹlera: Látorí tábìli Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 17

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu ayọ ti o ga ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ogun 2025. Adura mi ni pe ki ọrọ Ọlọrun ti o n fi igba gbogbo tọ ọ wa ninu ijọ yi ma kuna lati mu ifẹ rẹ ṣẹ ninu aye rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, igbakugba ti Ọlọrun ba sọrọ, nṣe ni yoo duro ti ọrọ naa lati mu wa si imuṣẹ (Jeremáyà 1:12). Ṣugbọn imuṣẹ ọrọ Ọlọrun ko ki i ṣadede waye. Iha ti awọn ti O n ba sọrọ ba kọ si ọrọ rẹ naa tun ṣe pataki. Aijẹbẹ, ọrọ rẹ le ma jẹ mimuṣẹ ninu aye wọn.

Fun apẹrẹ, bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun ṣe ileri lati fi ilẹ Kenani fun awọn ọmọ Isiraẹli, ọpọ ninu wọn ti o jade lati Ijibiti wa ni ko le wọ ibẹ. Ki ni idi? Idi ni pe iha ti wọn kọ si ileri Ọlọrun ko dara. Wọn ko gbagbọ pe Ọlọrun le mu ileri ti O ṣe fun wọn ṣẹ. Nitorina, nigba ti O sọ fun wọn pe ki wọn wọ ilẹ naa lọ lati gba a, wọn kọ lati ṣe bẹẹ. (Wo: Númérì 13-14)

Wayi o, nitoripe wọn kọ lati wọ ilẹ Kenani lati gba a nigba ti Ọlọrun sọ wipe ki wọn ṣe bẹ ẹ, Oun naa wa pinnu pe Oun ko ni fun wọn ni ilẹ naa mọ afi awọn ọmọ wọn. Ki wa ni o pada ṣẹlẹ si wọn? Nṣe ni wọn ranmu ninu aginju titi gbogbo wọn fi ṣegbe.

Nibakanna, a ri ọpọ Kirisitiẹni loni ti o n ranmu laye nitoripe wọn kọ lati tẹwọgba ọrọ Ọlọrun fun aye wọn, ki wọn ṣi ṣiṣẹ tọ ọ. Ki wa ni idi ti wọn fi kọ lati tẹwọgba ọrọ rẹ, ki wọn si ṣiṣẹ tọ ọ? Ibẹru jẹ ọkan lara awọn idi wọnyi. Ti awọn eniyan ba n bẹru bi nkan ti yoo tẹyin ki wọn ṣiṣẹ lori ọrọ Ọlọrun yọ yoo ṣe ri, wọn le ma ṣiṣẹ lori rẹ.

Lotitọ, ko si ẹnikẹni ninu wa ti o le fọwọ sọya sọ wipe bi nkan ti yoo tẹyin ki a ṣiṣẹ lori ọrọ Ọlọrun yọ yoo ṣe ri re e. Ṣugbọn ti a ba ni igbẹkẹle ninu pe Ọlọrun ko ni lailai doju ti wa, a o ṣiṣẹ lori ọrọ rẹ, bi o tilẹ jẹ wipe a ko mọ nkan ti yoo tẹyin rẹ jade. Ti a ba si ṣe eyi, o di dandan ki a ri ogo rẹ.

Igberega tun jẹ idi miran ti awọn kan ko ki i fi ṣiṣẹ lori ọrọ Ọlọrun. Awọn wọnyi, bi Ọba Sọọlu ati Ọba Asa, ro wipe awọn mọ ju Ọlọrun lọ ati wipe ete ti wọn san ju ki wọn fi igbẹkẹle wọn sinu rẹ, ki wọn si ṣe ohun yowu ti O ba sọ fun wọn pe ki wọn ṣe. Ṣugbọn bibeli sọ wipe omugọ Ọlọrun san ju ọgbọn eniyan lọ. O tun sọ fun wa pe ki a ma gbẹkẹle oye wa tabi ki a ro wipe a gbọn loju ara wa ni mimojuto ọrọ aye wa. Aijẹbẹ, bi o ti ṣe ri fun Sọọlu ati Asa, ko ni pẹ ti yoo fi han si awa naa pe omugọ ni ọgbọn wa. (Wo: 1 Sámúẹ́lì 15; 2 Kíróníkà 16; Ìwé Òwe 3:5-7; 1 Kọ́ríntì 1:25)

Lafikun, a ri awọn ti ko ki i ṣiṣẹ lori ọrọ Ọlọrun nitoripe wọn ko ki i farabalẹ tẹti si nkan ti o n sọ fun wọn. Ki ni idi? Idi ni pe ifẹ owo, ifẹ iyi, ifẹ faaji tabi ifẹ ipo ko jẹ ki wọn roju-raaye. Nkan ti ko wa ye wọn ni wipe awọn nkan wọnyi ko le fun wọn ni itẹlọrun laye. Ọlọrun nikan ni o le fun wọn ni itẹlọrun. Niwọn igba ti wọn ko si wa ni kọbiara si nkan ti O n sọ fun wọn, nṣe ni wọn o ma fi ayeraye le itẹlọrun kiri, ti wọn ko si ni ri.

Wayi o, mo le ma mọ idi ti iwọ naa ko ki i fi ṣiṣẹ lori ọrọ Ọlọrun ti o n tọ ọ wa bi o ti ṣe tọ. Ṣugbọn mo mọ wipe ti o ko ba ṣiṣẹ lori ọrọ rẹ, ko si bi aye rẹ ṣe fẹ fidi mulẹ ninu ifẹ rẹ. Ti o ba wa fẹ ki aye rẹ fi idi mulẹ ninu ifẹ rẹ, gbe ibẹru, igberaga tabi ohunkohun ti ko jẹ ki o roju-raaye ti ṣẹgbẹ kan, ki o ba a le kọbiara si gbigbọ ati ṣiṣe ọrọ Ọlọrun ni ẹkunrẹrẹ. Njẹ ki o gba okun lati ṣe eyi ni kiakia, ki aye rẹ ba a le da ohun gbogbo ti Ọlọrun fẹ ki o da. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ìdì tí wọn kò kí fí ṣiṣẹ́ lórí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run | Lati ọwọ: J.O. Lawal | Ọjọ: Ogun 23, 2026 | Atẹlera: Látorí tábìli Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 17 Read More »

Akori: Pẹ̀lú wa tàbí láìsí waati ọwọ: J.O. LawalỌjọ: Ogun 16, 2026Atẹlera: Látorí tábìli Pásítọ̀Nọ́múbà: Vol. 15, No. 16

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai-lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu ayọ ti o ga ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ògún 2026. Adura mi ni pe ki Ọlọrun ma a fi igba gbogbo jẹ ki ọkan rẹ wa ni pipe pẹlu rẹ, ki O ba a le ri ọ lo lati gbe ijọ rẹ ro lati jẹ ohun ti O fẹ ki o jẹ. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ẹni kan ṣoṣo ti O le gbe ijọ Ọlọrun ro ni Jesu Kirisiti Oluwa wa. Wo nkan ti O fi igbakan ri sọ fun awọn ọmọ ẹyin rẹ lori eyi:

“Emi wi fun ọ, iwọ ni Peteru ati pe ori apata yii ni emi yoo kọ ijọ mi le, ati ẹnu-ọna ipo-oku ki yoo le bori rẹ.” (Mátíù 16:18)

Ṣe o ri bayẹn? Tani o ni ijọ? Jesu Oluwa ni. O wa ṣeni laanu pe ọpọ awọn adari ijọ loni ni wọn ro wipe awọn ni wọn ni awọn ijọ Ọlọrun ti o wa ni abẹ isakoso wọn. Ṣugbọn awọn kọ ni wọn ku fun ẹṣẹ awọn ti o wa ni abẹ iṣakoso wọn. Lafikun, awọn kọ ni wọn tun awọn ti o wa ni abẹ iṣakoso wọn da.

Ẹni ti o ku fun ẹṣẹ gbogbo wa ni Jesu Oluwa. Ẹni ti O si tun gbogbo wa da ni Ọlọrun. Ti ẹnikẹni ba wa n gbiyanju lati gba aaye wọn, o di dandan ki ẹni naa ba ara rẹ ninu iyọnu bi o pẹ bi o ya. Idi si ni yi ti ọpọ awọn adari awọn eniyan Ọlọrun fi ṣe ba ara wọn ninu oniruuru iyọnu ti wọn ko tilẹ le ba ẹnikankan sọ loni. Wọn ti n gbiyanju lati gba aaye ti ko ki i ṣe ti wọn ninu aye awọn eniyan Ọlọrun.

Ni kukuru, niwọn igba ti o jẹ wipe Oluwa ni ẹni ti O ni ijọ, Oun nikan naa ni O le gbe ijọ rẹ ro lati jẹ ohun ti o yẹ ki o jẹ. O si ti sọ wipe Oun yoo ṣe bẹẹ gẹgẹ. Lọna wo? Ọkan lara ọna ti O fi n ṣe eyi ni nipa ṣiṣe ọmọ ijọ kọọkan yẹ lati ṣe awọn nkan ti yoo ja si igbero gbogbo awọn ọmọ ijọ yoku lapapọ.

Nitorina, ti o ba n ṣe ohunkohun ninu ijọ lọwọlọwọ yi ti o n bukun fun awọn eniyan Ọlọrun, nṣe ni ki o mọ wipe Jesu Kirisiti Oluwa funrarẹ ni O n ṣiṣẹ nipasẹ rẹ. Ti O ba si fẹ ki O ṣiṣẹ nipasẹ rẹ siwaju si lati bukun fun ọpọ eniyan si, nṣe ni ki o rẹ ara rẹ silẹ niwaju rẹ, ki o si fi ara rẹ si arọwoto rẹ.

Ọpọ ni o wa ninu ijọ loni ti Oluwa ko lo nitori igberaga wọn. Awọn wọnyi ro wipe ti awọn ko ba ṣe awọn nkankan ninu ijọ Ọlọrun, awọn nkan naa ko ni lailai jẹ ṣiṣe. Ṣugbọn nkan ti ko ye wọn ni pe wọn ko le ṣe ohun rere kankan fun ijọ kankan ti ko ba ṣe wipe Oluwa funrarẹ ba jẹ ki o ṣeeṣe fun wọn lati ṣe e. Niwọn igba ti eyi si ri bẹ ẹ, O le fi awọn miran rọpo wọn ni ọjọkọjọ ati ni asikokasiko.

Siwajusi, a ri ọpọ ninu ijọ ti Oluwa ko ma a lo nitoripe wọn ko fi ara wọn si arọwọto rẹ. Gbogbo igba ni wọn ma n ri awawi kan tabi omiran lati ma wa ni ibi ti O fẹ ki wọn wa ati lati ma ṣe ohun ti O fẹ ki wọn ṣe. Irufẹ awọn wọnyi n fojufo pe O le fi awọn miran rọpo wọn ti wọn ko ba tete ronupiwada.

Ki a ma fọrọgun, koko nkan ti a n sọ ni pe Oluwa le gbe ijọ rẹ ro yala pẹlu mi tabi laisi mi. Ti mo ba rẹ ara mi silẹ, ti mo si fi ara mi si arọwọto rẹ, yoo lo mi. Ṣugbọn ti mo ba n rin ninu igberaga tabi ti mo kọ lati fi ara mi si arọwọto rẹ, O di dandan ki o wa awọn miran ti yoo lo lati gbe ijọ rẹ ro. Eyi si wa le gba asiko nitootọ. Ṣugbọn O di dandan ki O ṣe ohun ti o yẹ. Njẹ yoo wa pin mi ni ere fun fifi ara mi si ipọ alaiwulo fun un bi? Rara o!

Nitorina, ẹ jẹ ki a ma a fi igba gbogbo fi si ọkan pe Oluwa yoo gbe ijọ rẹ ro yala pẹlu wa tabi laisi wa. Nipa ba yi, a o le rẹ ara wa silẹ ati fi ara wa si arọwọto rẹ ni igbakugba ati lasiko-kasiko. Nigba ti asiko ba si to, a o gba ere ti o ga lati ọwọ rẹ.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Akori: Pẹ̀lú wa tàbí láìsí waati ọwọ: J.O. LawalỌjọ: Ogun 16, 2026Atẹlera: Látorí tábìli Pásítọ̀Nọ́múbà: Vol. 15, No. 16 Read More »

Ìbàlẹ-ọkàn nínú túbú | Láti ọwọ́: Omotola Dunsin Babarinde | Ọjọ́: Ògún 09, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 15

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu idunnu ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu yi. Adura mi ni pe ki o ni iriri ibalẹ-ọkan Ọlọrun ti o kọja oye eniyan nibikibi ti ara ba ti n ni ọ ninu aye rẹ, ki ayọ rẹ ba a le kun. Amin.

Bi a ti ṣe n bẹrẹ ọsẹ yi, mo fẹ gba ọ niyanju pẹlu itan Pọọlu ati Sila ninu tubu ni ilu Filipi. Awọn ọkunrin wọnyi ni a mu, ti a na, ti a si tun sọ sinu tubu nitoripe wọn tu ẹrubinrin kan silẹ kuro lọwọ ẹmi eṣu ti o n lo o. Ṣugbọn, dipo ti eyi yoo fi fa irẹwẹsi si ọkan wọn, nṣe ni wọn bẹrẹ si ni gbadura, ti wọn si n yin Ọlọrun. Wo nkan ti Luuku sọ nipa eyi:

“Ṣugbọn larin ọganjọ Paulu on Sila ngbadura, nwọn si nkọrin iyìn si Ọlọrun: awọn ara tubu si ntẹti si wọn.” (Ìṣe Àpọ́sítélì 16:25)

Wayi o, bi gbogbo wa ti ṣe mọ, inu tubu jẹ ibi-ìdè, ibi inira ati ibi ti ireti ti pin. Sibẹsibẹ, Pọọlu ati Sila ni iriri ibalẹ-ọkan Ọlọrun ninu tubu. Itan wọn wa kọ wa pe awọn iṣẹlẹ aye wa ko nilo lati sakoso ọkan wa. Idi si ni pe lati ipasẹ idurotini Ọlọrun ni ibalẹ-ọkan otitọ ti n wa, eyi ti ko ni nkankan ṣe pẹlu ki iṣorọ ma wa.

Ki wa ni a le tipasẹ Pọọlu ati Sila kọ? Akọkọ ni pe ibalẹ-ọkan a ma wa nipasẹ gbigbẹkẹle Ọlọrun. Bi o tilẹ jẹ wi pe a na wọn, ti a si tun de wọn mọlẹ, Pọọlu ati Sila ko kun tabi ṣaroye. Dipo eyi, nṣe ni wọn gbẹkẹle Ọlọrun ninu inira wọn. Àìsáyà 26:3 sọ wipe, “Iwọ o pa a mọ li alafia pipé, ọkàn ẹniti o simi le ọ: nitoriti o gbẹkẹle ọ.” Nitorina, ti a ba fi igbẹkẹle wa sinu Ọlọrun, yoo fun wa ni ibalẹ-ọkan ti o peye.

Ekeji, a kọ nipasẹ wọn pe ibalẹ-ọkan a ma ja si iyin. Dipo ti wọn yoo fi ma kun sinu, Pọọlu ati Sila gbadura, wọn si tun kọ orin iyin si Ọlọrun lọganjọ oru. Ijọsin wọn fi han wa pe ọdọ Ọlọrun ni ibalẹ-ọkan ti ma n wa. Fílípì 4:7 sọ wipe, “Ati alafia Ọlọrun, ti o jù ìmọran gbogbo lọ, yio ṣọ ọkàn ati ero nyin ninu Kristi Jesu.” Eyi tunmọ si pe nibi ti ibalẹ-ọkan ba ti wa, ọkan wa yoo wa balẹ to lati yin Ọlọrun.

Ẹkẹta, a kọ lati ara nkan ti o ṣẹlẹ si Pọọlu ati Sila ninu tubu pe ibalẹ-ọkan a ma ṣiṣẹ fun itusilẹ agbara Ọlọrun. Bi wọn ti n yin Ọlọrun pẹlu ọkan ti o balẹ lẹkunrẹrẹ, Ọlọrun jẹ ki ilẹ mi titi, awọn ilẹkun tubu ṣi, a si ja gbogbo ide. Wa ranti wipe Sáàmù 34:19 sọ wipe, “Ọ̀pọlọpọ ni ipọnju olododo; ṣugbọn Oluwa gbà a ninu wọn gbogbo.” Nitorina, bi o ti wu ki isọro wa to, ibalẹ-ọkan lati ọdọ Ọlọrun le tu agbara rẹ silẹ lati yanju gbogbo wọn lẹyọkọọkan.

Ẹkẹrin, a kọ lati ara wọn pe iriri ibalẹ-ọkan lati ọdọ Ọlọrun le bukun fun awọn miran. Oluṣọ tubu ati idile rẹ gbagbọ ninu Jesu, wọn si di ẹni igbala nitori iriri ibalẹ-ọkan ti Pọọlu ati Sila ni ninu tubu. Mátíù 5:16, “Ẹ jẹ ki imọlẹ nyin ki o mọlẹ tobẹ̃ niwaju enia…” Nitorina, ti a ba fi aaye gba ibalẹ-ọkan lati ọdọ Ọlọrun lati jọba ninu aye wa, yoo jẹ ki awọn miran wa si ọdọ Ọlọrun nitori wa.

Ni akotan, ibalẹ-ọkan Ọlọrun wa fun wa pẹlupẹlu ni gbogbo asiko ti nkan nira. Adura ati iyin yoo fun igbagbọ wa ni okun ni asiko idanwo. Ọlọrun le sọ inu tubu di ile ẹri jijẹ. Igbagbọ rẹ ti ko yẹsẹ ni asiko iṣoro le dari awọn miran sọdọ Kirisii. Nitorina, bi o tilẹ wa ninu tubu loni, yala tubu aini, tubu aisan, tubu isoro ẹbi, tubu ijani-ni-tanmọ tabi tubu inunibini, ma ṣe sọ ireti nu. Ti o ba tẹsiwaju lati fi igbẹkẹle rẹ sinu Ọlọrun, ti o n gbadura si, ti o si n yin-in, yoo fun ọ ni ibalẹ-ọkan ati idande ni asiko ti o tọ.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ìbàlẹ-ọkàn nínú túbú | Láti ọwọ́: Omotola Dunsin Babarinde | Ọjọ́: Ògún 09, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 15 Read More »

Fún wọn ní ìdí tí ó dájú | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ògún 02, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 14

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Pẹlu idunnu ti o ga ni mo ki ọ kaabọ sinu oṣu Ògún 2026. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun mu gbogbo eto rere ti O ni fun aye rẹ ninu oṣu naa wa si imuṣẹ, ki O si tun lo ọ lati mu eto rere rẹ fun aye ọpọ awọn miran naa wa si imuṣẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, bi o ti wu ki eniyan ma ja mọ nkankan to tabi ki o buru to laye yi, Ọlọrun si le mu eto rere rẹ fun aye wọn wa si imuṣẹ, ki O si tun lo wọn gẹgẹ bi irinṣẹ lati bukun fun aye wọn miran. Nkan ti O nilo ni ki wọn tẹti silẹ bẹlẹjẹ lati gbọ nkan ti O fẹ sọ fun wọn. Ki wọn si to mọ nkan ti o n ṣẹlẹ si wọn, yoo ti yi ohun gbogbo pada si rere fun wọn.

Fun apẹrẹ, nigba ti Jesu Oluwa wa pade arabinrin Samaria kan ni eti kanga Jakọbu ti o wa ni Sikari, nkan kan ṣoṣo ti O fẹ ni ki arabinrin yi tẹti si ohun ti O fẹ sọ fun-un. Ṣe o wa ṣetan lati gbọ tirẹ? Rara o! O kan fẹ pọn omi, ki o si poora ni. (Wo: Jòhánù 4)

Ki wa ni o fa ti ko fi fẹ ba ẹnikẹni sọrọ ni asiko naa? Idi ni pe o n gbiyanju lati sa fun otitọ ọrọ lori awọn iṣoro aye rẹ. Ṣugbọn nigba ti Oluwa, nipasẹ ifihan Ọlọrun, bẹrẹ si ni tu aṣiri otitọ ti o n sa a fun si i, o bẹrẹ si ni tẹti silẹ lati gbọ nkan ti O fẹ sọ. Nigba ti Oluwa si ṣetan pẹlu rẹ, nṣe ni o sure lọ sinu ilu rẹ lati pe gbogbo awọn ti o ri lati wa gbọ ọrọ rẹ. Iwọ naa wo nkan ti a sọ lori eyi ninu bibeli:

“Nigbana li obinrin na fi ladugbo rẹ̀ silẹ, o si mu ọ̀na rẹ̀ pọ̀n lọ si ilu, o si wi fun awọn enia pe, Ẹ wá wò ọkunrin kan, ẹniti o sọ ohun gbogbo ti mo ti ṣe ri fun mi: eyi ha le jẹ Kristi na? Nigbana ni nwọn ti ilu jade, nwọn si tọ̀ ọ wá.” (Jòhánù 4:28-30)

Njẹ o ri bayẹn? Nkan ti Jesu ba obinrin yi sọ ba ọkan rẹ pade debi wipe o wọ inu ilu rẹ lọ lati lọ pe awọn ti o wa nibẹ wa lati wa ri Jesu. Ṣugbọn arabinrin yi ki i ṣe ẹnikan ti a le pe ni obinrin rere. O jẹ enikan ti o ti ni ọkọ marun ọtọọtọ. Ọkunrin ti o si wa pẹlu rẹ ni asiko ti o pade Jesu yi gan ko ki i ṣe ọkọ rẹ. Ẹnikan ti wọn kan jọ n ṣe iṣekuṣe papọ ni ki a pe. Nitorina, obinrin yi ko le jẹ ẹnikan ti o ni orukọ rere ninu ilu naa.

Ṣugbọn bi o tilẹ jẹ wipe Oluwa mọ ohun gbogbo nipa iwa buburu rẹ, ko da a lẹbi rara. O kan ba sọrọ lori pataki ki o mọ Ọlọrun lotitọ, ki o si bẹrẹ si ni sin-in ninu ẹmi ati ni ododo ni. Eyi lo si yi aye rẹ pada. Eyi ni o jẹ ki o gbagbẹ nipa pe oun ko ni orukọ rere, ti o si sure lọ sọ fun gbogbo awọn ti o le ri ninu ilu rẹ lati wa wo Jesu. Jesu Oluwa si wa tipasẹ rẹ ni anfaani lati bukun fun ọpọ eniyan ninu ilu rẹ.

Wayi o, ti Ọlọrun ba le lo obinrin ti ko ni orukọ rere yi lati yi aye ọpọ pada ninu ilu rẹ, wa ro nkan ti O le ṣe pẹlu awọn ti o ni orukọ rere. Sibẹsibẹ, ko ki i ri ọpọ awa ti a ni orukọ rere lo lati bukun fun awọn ti o wa ni ayika wa. Ki ni idi? Idi ni pe a ko ki i fun wọn ni idi ti o daju lati tọ Ọlọrun wa nipasẹ igbagbọ ninu Kirisiti Jesu.

Arabinrin Samaria yi fun awọn ara ilu rẹ ni idi to daju lati wa sọdọ Jesu Oluwa. Ko kan ba wọn sọrọ nipa iriri rẹ pẹlu Jesu ṣakala. Ti o ba jẹ wipe o kan lọ sọrọ sakala nipa rẹ ni, wọn ko ba ma ti tọ ọ wa fun igbala. Nitorina, ti a ba fẹ ki awọn eniyan tipasẹ wa tọ Jesu Oluwa wa wa, ki wọn si di alabukunfun, a ko le ma sọrọ sakala nipa rẹ. Ti a ko ba si ni sọrọ sakala nipa rẹ, yoo jẹ wipe aye wa ti gba iyipada nipasẹ rẹ nitootọ niyẹn.

Ṣe aye rẹ ti wa gba iyipada nipasẹ Jesu Kirisiti Oluwa wa nitootọ? Ti o ba ti gba iyipada nipasẹ rẹ, bẹrẹ si ni fun awọn ti o wa ni ayika rẹ ni idi ti o daju lati tọ ọ wa, idi ti o daju lati gbọ ọrọ rẹ, idi ti o daju lati gbadura si i ati idi ti o daju lati fi aye wọn fun. Bi o ba si ṣe n ṣe eyi, Ẹmi Ọlọrun yoo ma a ba ọ ṣiṣẹ lati yi aye wọn pada ati lati mu ogo wa fun Ọlọrun.

Kí o ní oṣù Ògún 2026 alárinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Fún wọn ní ìdí tí ó dájú | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ògún 02, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 14 Read More »