O kàn ń tan ara rẹ jẹ ní | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 16, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 29

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lọpọlọpọ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ kẹta ninu oṣu Belu 2025. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ma a fi ojoojumọ fun ọ ni okun lati mu ọrọ rẹ ni ọkunkundun, ki o ba a le so eso ti o yẹ ki o so ninu aye rẹ. Amin.

Jakọbu, ninu lẹta rẹ, sọ eyi fun wa: “Ṣugbọn ki ẹ jẹ oluṣe ọ̀rọ na, ki o má si ṣe olugbọ́ nikan, ki ẹ mã tàn ara nyin jẹ.” (Jákọ́bù 1:22) Ṣe ko ki i ṣe nkan ti o dara ni lati gbọ ọrọ Ọlọrun ni? Nkan ti o dara ni lati ṣe bẹ ẹ. Johanu tilẹ sọ fun wa ninu iwe Ifihan pe awọn odiwọn ibukun kan wa ti o ma n tẹle kika ọrọ Ọlọrun tabi gbigbọ ọ (Ìfihàn 1:3).

Amọ ṣa o, gbigbọ ọrọ Ọlọrun tabi kika a ko ma to. A tun nilo lati ṣe nkan ti ọrọ naa n sọ. Aijẹbẹ, ifẹ Ọlọrun ko ni wa si imuṣẹ ninu aye wa tabi lorilẹ aye. Niwọn igba ti ifẹ rẹ ko ba si ma wa si imuṣẹ ninu aye wa tabi ninu aye ti a wa, a ko le ni iriri alaafia ati ayọ ti a n fẹ ni.

Jesu Oluwa wa na sọ itan kan fun wa ni ibamu pẹlu ọrọ yi. O da lori baba kan ti o ni ọmọkunrin meji, ti o si sọ fun ọmọkunrin rẹ akọkọ, “Lọ ṣiṣẹ ninu ọgba ajara loni.” Nṣe wa ni ọdọmọkunrin naa sọ wipe oun kọ ni lọ. Nitorina, baba yi lọ si ọdọ ọmọkunrin rẹ keji, o si sọ fun pe, “Lọ ṣiṣẹ ninu ọgba ajara loni.” Ọdọmọkunrin naa si sọ wipe oun o lọ. Ṣugbọn ko lọ rara. Ọmọkunrin baba yi akọkọ, ẹwẹ, wa pada ni iyipada ọkan, o si lọ ṣiṣẹ ninu ọgba ajara baba rẹ. (Wo: Mátíù 21:28-31)

Ibere wa ni pe, “Tani o ṣe ifẹ baba rẹ ninu awọn ọdọmọkurin mejeeji yi?” Ọmọkunrin baba yi akọkọ ni o ṣe ifẹ rẹ. Ọmọkunrin rẹ keji ti o ṣe bi ẹni pe oun jẹ onigbọran ọmọ ko ṣe ifẹ baba rẹ rara. Nitorina, ti baba yi ba fẹ pin ẹnikẹni lere fun ṣiṣe ifẹ rẹ lọjọ naa, ọmọkunrin rẹ akọkọ ni yoo pin lere, ko ki i ṣe ọmọkunrin rẹ keji.

O wa ṣeni laanu pe, pupọ ninu wa ni o dabi ọmọkunrin baba yi keji. Nigba ti ọrọ Ọlọrun ba n tọ wa wa, nṣe ni a o ma mi ori wa ni ibamu pẹlu ọrọ naa, ti a o si tun ma pariwo fun ayọ nigba miran nitori nkan ti Ọlọrun n sọ fun wa. Ṣugbọn ti o ba di ki a ṣiṣẹ tọ nkan ti a n gbọ, ọtọ ni nkan ti a o ma ṣe. Wa gbiyanju a ti wo bi eyi yoo ṣe ma dun Ọlọrun lọkan to.

Ki a ma fọrọgun, Jakọbu sọ fun wa pe awọn ti o ba n ṣe ba yi kan n tan ara wọn jẹ ni. Idi si ni pe ọrọ Ọlọrun ti wọn ko ṣiṣẹ le lori ko le ṣe aye wọn tabi aye ti wọn wa ninu rẹ ni anfaani. Ko ni yi aye wọn tabi ọrọ aye wọn pada. Nitorina, nṣe ni wọn kan n fi akoko, okun ati owo ti wọn n ko sori gbigbọ tabi kika ọrọ naa ṣofo.

O wa ṣeeṣe ki o jẹ wipe bi iwọ naa ṣe ri ni eyi. O ma n ṣaba ṣe bi ẹni pe o n fọwọsowọpọ pẹlu Ọlọrun ti ọrọ rẹ ba n tọ ọ wa. Ṣugbọn nkan ti o wa ni ọkan rẹ ni iwọ yoo papa ṣe, ko ki i ṣe nkan ti O fẹ ki o ṣe. Nṣe ni o kan n tan ara rẹ jẹ. Nitorina, gbogbo asiko, okun ati owo ti o n na lori gbigbọ ati kika ọrọ rẹ di dandan ki o ṣofo. Idi si ni pe ọrọ Ọlọrun ti o ko ni ṣiṣẹ le lori ko le yi aye rẹ tabi igba pada fun ọ.

Wayi o, emi ko fẹ fi akoko, okun ati owo ti mo n na lori gbigbọ tabi kika ọrọ Ọlọrun ṣofo mọ. Dipo eyi, mo fẹ ki ọrọ rẹ ṣiṣẹ ninu aye mi, ki o si ṣe aye mi ni ohun gbogbo ti O fẹ ki o jẹ. Idi si niyi ti ma a fi ma fi ojoojumọ bere fun okun lati ma kan jẹ olugbọ ọrọ rẹ lasan ṣugbọn oluṣe ọrọ rẹ pẹlu. Njẹ iwọ naa yoo ṣe bẹẹ gẹgẹ bi? Ti iwọ naa yoo ba ṣe bẹẹ gẹgẹ, njẹ ọrọ rẹ ti o n gbọ ko tun ni ṣofo ninu aye rẹ mọ ṣugbọn yoo ma a so eso ti Ọlọrun fẹ ri ninu rẹ.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *