Ẹ̀ṣẹ̀ ÉlìLáti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 19, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 51

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Igbe 2026. Mo gbadura pe ki Ọlọrun ma jẹ ki o lugbadi idajọ rẹ lori ọkankan ninu awọn ti o wa ninu aye rẹ tabi ni ayika rẹ. Amin.

Wayi o, mo gba adura yi fun ọ nitoripe ko ki i ṣe gbogbo igba ti awọn eniyan ba ni iriri idajọ Ọlọrun naa ni o jẹ nitoripe awọn funrawọn buru ni. Igba miran wa ti awọn eniyan a ma a ni iriri idajọ Ọlọrun nitoripe wọn kuna lati lo aṣẹ wọn lati ṣe idajọ awọn ti o wa ni abẹ iṣakoso wọn. Fun apẹrẹ, Ọlọrun sọ eyi fun Samuẹli nipa alufa Eli:

“Nitoriti emi ti wi fun u pe, emi o san ẹsan fun ile Eli titi lai, nitori iwa buburu ti on mọ̀, nitori awọn ọmọ rẹ̀ ti sọ ara wọn di ẹni ẹgàn, on kò si da wọn lẹkun.” (1 Sámúẹ́lì 3:13)

Ki ni idi ti Ọlọrun ṣẹ fẹ ṣe idajọ idile Eli? Ṣe nitoripe ọkunrin naa buru ni? O ti o! Abi ṣe nitoripe awọn ọmọ rẹ kan buru ni? O ti o! Idi ti Ọlọrun fi fẹ ṣe idajọ idile rẹ ni pe o kuna lati mu awọn ọmọ rẹ so, bi o tilẹ jẹ wipe o mọ nipa ẹṣẹ wọn daadaa.

Ti Eli ko ba mọ nipa ẹṣẹ awọn ọmọ rẹ ni, Ọlọrun ko ma ba ti da lẹbi nitori wọn. Lafikun, ti Eli ko ba wa ni ipo ẹni ti o le da awọn ọmọ rẹ lẹkun ni, ki wọn ma ba a le ma ṣẹ si Ọlọrun bi o ti ṣe wu wọn, ko ba ma ti da a lẹbi nitori wọn. Ṣugbọn yatọ si pe o mọ nipa ẹsẹ wọn, o tun wa ni ipo lati da wọn lẹjọ ati lẹkun. Sibẹsibẹ, o kuna lati ṣe eyi. Nitorina, Ọlọrun sọ fun pe Oun yoo ṣe idajọ idile rẹ fun ẹṣẹ awọn ọmọkunrin naa.

Njẹ ki wa ni idi ti Ọlọrun fi kọkọ sọ fun un nipa idajọ rẹ ti o n bọ ṣaju asiko idajọ naa? Idi ni ki o ba a le ṣe ohun ti o tọ pẹlu ikanju. Ṣe o wa ṣe ohun ti o tọ? Rara o, ko ṣe e. Dipo eyi, esi ti o fọ ni pe aaye pọ fun Ọlọrun lati ṣe ohun yowu ti o ba tọ loju rẹ lori ọrọ naa. Eyi jasi pe, ni titiẹ, ko ṣetan lati tun yọ ara rẹ lẹnu lori nkan ti awọn ọmọkunrin rẹ n ṣe mọ. (Wo: 1Sámúẹ́lì 3:18)

Ki wa ni eyi n kọ wa, ki a ma fọrọgun? Oun naa ni pe ti Ọlọrun ba fi awọn eniyan si abẹ iṣakoso wa, ko reti pe ki a fi aye gba wọn lati ma a ṣe bi o ba ṣe wu wọn. Dipo eyi, nkan ti O n reti ni pe ki a ma a lo aṣẹ wa lati fi wọn si aaye wọn, ti wọn ba n ṣe radarada. Aijẹbẹ, nṣe ni a o ma da ẹṣẹ Eli. Ti eyi ba si ri bẹ, igbakugba ti Ọlọrun ba da si ọrọ naa lati ṣe idajọ iwa ika ti a kọ lati ṣe idajọ rẹ, o di dandan ki awa naa kopa ninu idajọ naa, ayafi ti a ba ṣaanu fun wa. Ta wa ni o mọ ọna ti Ọlọrun yoo gba ṣe idajọ?

Nitorina, ma ṣe da bi Eli ti o kọ lati ṣiṣẹ lori ikilọ Ọlọrun lati ṣe idajọ awọn ọmọ rẹ nitoripe radarada wọn su u. Dipo eyi, nṣe ni ki o bẹrẹ si ni lo aṣẹ rẹ lati fi gbogbo nkan si aaye wọn nibikibi ti o ba ti ni aṣẹ lati ṣe bẹ ẹ. Nipa bayi, iwọ yoo le pa ara rẹ mọ lati ma kopa ninu idajọ awọn alaigbọran.

Siwaju si, ma ṣe jẹ ki inu bi ọ nigba ti awọn ti o ni aṣẹ lori rẹ ko ba fi aaye gba ọ lati ma ṣe radarada labẹ isakoso wọn. Idi si ni pe ifẹ Ọlọrun ni wọn nṣe. Yatọ si iyẹn, nipa bi wọn ko ṣe fi aaye gba ọ lati ma ṣiwawu labẹ isakoso wọn, nṣe ni wọn n pa ọ mọ kuro labẹ idajọ Ọlọrun. Nitorina, nṣe ni o yẹ ki o ma dupẹ lọwọ wọn fun bi wọn ṣe jẹ adari ti o mọ ojuṣe wọn. Aijẹbẹ, o le ṣe ara rẹ leṣe nipasẹ idajọ Ọlọrun, ti o ba kọ lati gba ibawi. Mo gbadura pe iru eyi ko ni jẹ ipin rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *