Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Pẹlu idunnu ti o ga ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o so oṣu Igbe ati Èbìbí 2026 papọ. Adura mi ni pe ki Ọlọrun, ni kiakia, ya aye rẹ ya ohun gbogbo ti o n mu akude ba didara rẹ ninu rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.
Mo gba adura yi fun ọ nitoripe a ma n ri awọn igba ti o jẹ wipe idi ti awọn nkan rere ti Ọlọrun n ṣe ninu aye awọn eniyan rẹ ko ki i fi ja mọ nkankan ni pe awọn nkan kan ninu aye wọn n mu akude ba wọn. Ti a ko ba si mojuto awọn nkan wọnyi, ko si nkan rere kankan ti O le ṣe fun wọn ti yoo fun wọn ni itẹlọrun ati isinmi ni aye.
Fun apẹrẹ, a ko eyi sinu bibeli nipa ọkunrin kan ti a n pe ni Naamani:
“NJẸ Naamani, olori-ogun ọba Siria, jẹ enia nla niwaju oluwa rẹ̀, ati ọlọla, nitori nipa rẹ̀ ni Oluwa ti fi iṣẹgun fun Siria: on si jẹ alagbara akọni ọkunrin ṣugbọn adẹtẹ̀ ni.” (2 Àwọn Ọba 5:1)
Ta ni o mu Naamani di ẹni nla, bi a ti ṣe ri ninu ẹsẹ bibeli yi? Ọlọrun ni. Oun ni O sọ di ẹni ti gbogbo eniyan ni orilẹ-ede rẹ, pẹlupẹlu ọba rẹ, ka si ẹni pataki ati ẹni-ọwọ. Ṣugbọn pẹlu gbogbo awọn nkan ti Ọlọrun ṣe fun-un wọnyi, ko ki ṣe ẹnikan ti inu rẹ dun, ti o si tun ni balẹ ọkan tan yanyan. Ki ni idi? Adẹtẹ ni. Eyi jasi pe, o jẹ ẹnikan ti wọn yo pada ya sọtọ kuro lọdọ gbogbo awọn ti o fẹran rẹ, ti yoo si wa ma a da gbe. Aijẹbẹ, wọn le ko ẹtẹ rẹ.
Ki wa ni titobi rẹ yoo ja mọ? Ki ni ọrọ rẹ yoo ja mọ? Ki si ni gbogbo awọn iṣẹ akikanju ti Ọlọrun ti tipasẹ rẹ ṣe yoo ja mọ? Gbogbo awọn nkan wọnyi ni ẹtẹ rẹ yoo pada sọ di asan. Ẹtẹ rẹ ko ni jẹ ki o jẹ igbadun wọn lẹkunrẹrẹ tabi fun igba pipẹ. Ero lori eyi nikan gan an ro lati sọ di onibinujẹ ẹniyan.
Awa dupẹ pe Ọlọrun lo ọdọmọbirin ẹru kan ti a mu wa si ile rẹ lati ilẹ Isiraẹli lati ran an lọwọ lati ri iwosan rẹ gba. Ọdọmọbinrin yi sọ fun un nipa Wolii Eliṣa ati bi Ọlọrun ṣe le lo o lati wo ẹtẹ rẹ san. Nigba ti o si lọ si ọdọ eniyan Ọlọrun yi, a wo ẹtẹ rẹ san nitootọ. Nitorina, lati ọjọ naa lọ, o bẹrẹ si ni sin Ọlọrun, o si tun bẹrẹ si ni jẹ igbadun ohun rere gbogbo ti Ọlọrun ti ṣe fun pẹlu itẹlọrun ati laisi ibẹru.
Wayi o, Ọlọrun kanna ti O mojuto ẹtẹ Naamani le mojuto ohunkohun ti o n di ọ lọwọ lati jẹ igbadun didara rẹ ninu aye rẹ lẹkunrẹrẹ. Nkan ti o kan nilo lati ṣe ni ki o ke pe e fun iranlọwọ. Bi o si ti n ṣe eyi, gbogbo ‘Ṣugbọn’ ti o n sọ didara rẹ di alainitunmọ ninu aye rẹ ni a o mojuto. Iwọ yoo si wa bẹrẹ si ni jẹ igbadun awọn ibukun rẹ pẹlu itẹlọrun.
Ki o ni ọsẹ alarinrin.
Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)
Ki Olorun ki o ba gbogbo sugbon aye wa je patapata, ki ohun rere gbogbo ti aye wa to si ba le bere so jeyo lekunrere. Amin!
Ki Olorun ki o ba gbogbo sugbon aye wa je patapata, ki ohun rere gbogbo ti aye wa to si ba le bere si jeyo lekunrere. Amin!