Má mú Ọlọ̀run banújẹ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbì 03, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 01

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Pẹlu idunnu ti o ga ni mo ki ọ kaabọ sinu oṣu kaarun ọdun yi, iyẹn oṣu Èbìbí 2026. Adura mi ni pe ki Ọlọrun ma a fi igba gbogbo pa ọ mọ, ki o ma ba a ṣe ohunkohun ti yoo ba a ninujẹ, ti yoo si jẹ ki O yi ọkan rẹ pada lori mumi awọn eto rẹ fun aye rẹ ṣẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, mo gba adura yi fun ọ nitoripe o ṣeeṣe ki a mu inu Ọlọrun bajẹ. Bẹẹni, o ṣeeṣe ki a ba a ninujẹ nipa bi a ṣe n gbe aye wa ati nipa iha ti a n kọ si ọrọ rẹ. Idi si ni pe O fẹran wa. Kiki awọn ti a ba fẹran, ti a si n kẹ, ni wọn le ba wa ninujẹ tabi mu ọkan wa poruru. Awọn ti a ko ba fẹran ko le ba wa ninujẹ, bi o ti wu ki iwuwasi wọn si wa buru to. Ki a tilẹ sọ otitọ, ọpọ ninu wa ni ko tilẹ ni fẹ fi aye gba ẹnikẹni ti a ko fẹran lati ṣe ohunkohun ti yoo mu wa karisọ.

Ṣugbọn ti ẹnikan ti a fẹran, ti o si tobi lọwọ wa, ba bẹrẹ si ni wu iwa aikanisi si wa, inu wa ko ni dun rara. Ti irufẹ ẹni bẹ ẹ ba si tun wa tẹsiwaju lati ma mu inu wa bajẹ lọna yi, a le yi ọkan wa pada lori rẹ, ki a si mu ifẹ ti a ni si wọn kuro lọkan wa. Lẹyin eyi, wọn ko tun ni le jẹ igbadun ibaṣepọ wọn pẹlu wa bi wọn ti ṣe ma n jẹ tẹlẹ mọ.

Nibakanna, nitoripe Ọlọrun fẹran wa, a le mu inu rẹ bajẹ. Ti a ba si wa fi mimu inu rẹ bajẹ ṣe aṣa, asiko naa le de ninu eyi ti yoo yi ọkan rẹ pada lori wa ati lori eto rẹ fun wa. Bawo wa ni a ko ṣe ni fi aye wa ṣofo tabi pa aye wa run, ti eyi ba lọ waye?

Fun apẹrẹ, a sọ eyi nipa idi ti Ọlọrun fi yọ Ọba Sọọlu kuro ni ipo rẹ gẹgẹ bi ọba lori orilẹ-ede Isiraẹli:

“Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ Samueli wá wipe, Emi kãnu gidigidi ti emi fi Saulu jọba: nitoriti o ti yipada lẹhin mi, kò si mu ọ̀rọ mi ṣẹ. O si ba Samueli ninu jẹ gidigidi; on si kepe Oluwa ni gbogbo oru na.” (1 Sámúẹ́lì 15:10-11)

Njẹ o ri bayẹn? Inu Ọlọrun bajẹ nitoripe O fi Sọọlu ṣe ọba lori Isiraẹli. Ki si ni idi? Idi ni pe ọkunrin naa sọ di aṣa lati ma tapa si aṣẹ rẹ. Nkan ti o tun wa buru ju iyẹn lọ ni pe ko tilẹ ni ẹmi ironupiwada rara. O ni i lara lati fi tọkan-tọkan roninupiwada ti a ba ba a wi tabi sọ pe ki o tun iwa rẹ ṣe. Nitorina, Ọlọrun yi ọkan rẹ pada lori ọrọ rẹ, O si fi ẹlomiran rọpo rẹ.

Njẹ Sọọlu wa kaanu lori ọrọ yi bi, nigba ti Ọlọrun yi ọkan rẹ pada lori ọrọ rẹ, ki O si wa oju rẹ fun aanu? Rara o, ko ṣe bẹ ẹ. Nṣe ni o kan n ba iṣe rẹ lọ gẹgẹ bi ọba, bi igba ti ko si nkankan ti o ṣẹlẹ. Nitorina, o pada pa aye ara rẹ fun, o si sọ ohun rere yowu ti o ṣe fun orilẹ-ede Isiraẹli gẹgẹ bi ọba di asan.

Amọ ṣa o, bi a ti ṣe ri ninu akọsilẹ naa, Samuẹli ti ko ki i ṣe oun ni a rọ loye ko dẹkun lati ma kẹdun niwaju Ọlọrun fun ọkunrin yi. Lotitọ, nigba ti o tilẹ de ikorita kan, Ọlọrun ni lati sọ fun pe ki o ye kẹdun lori ọrọ Sọọlu mọ, ki o si lọ ta ororo si elomiran lori rọpo rẹ (1 Sámúẹ́lì 16:1). Ki wa lo fa ti o fi n kẹdun fun Sọọlu bi iyẹn? Idi ni pe o mọ babara ki a mu inu Ọlọrun bajẹ ati pataki ki a ronupiwada lotitọ ti a ba ti ṣe bẹ ẹ. Aijẹbẹ, a le pada fi aye wa ati oore-ọfẹ yowu ti a le ti ri gba lọwọ Ọlọrun ṣofo.

Eyi si wa ni idi ti a fi kilọ fun awa naa ninu Iwe Mimọ ni ọna yi:

“Ẹ má si ṣe mu Ẹmí Mimọ́ Ọlọrun binu, ẹniti a fi ṣe èdidi nyin dè ọjọ idande.” (Éfésù 4:30)

Njẹ o ri bayẹn? A gbọdọ ṣo ara wa ki a ma ba a fi ara wa jin fun ṣiṣe ohunkohun ti o le ba Ẹmi Ọlọrun ti O n gbe inu wa ninujẹ. Ti a ba si ti n ba ninu jẹ ni ọna kankan, nṣe ni ki a ronupiwada, ki a si wa oju rẹ fun aforiji ni kiakia. Aijẹbẹ, gẹgẹ bi Ọba Sọọlu, awa naa le pada fi gbogbo ifẹ ati oore-ọfẹ ti O ti tu si ori wa lẹkunrẹrẹ ṣofo. Njẹ ki eyi ma jẹ ipin wa, ni orukọ Jesu. Amin.

Kí o ní oṣù Èbìbí 2026 alárinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *