Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Èbìbí 2026. Adura mi ni pe ki Ọlọrun pa ọ mọ ninu ọsẹ yi ati ni gbogbo eyi ti o ku ninu ọdun yi kuro lọwọ awọn ika ati ọdaju eniyan nibikibi ti o ba ya si, ni orukọ Jesu. Amin.
Pọọlu, ninu lẹta rẹ keji si awọn ara Tẹsalonika, sọ eyi:
“Ati ki a le gbà wa kuro lọwọ awọn eniyan buburu ati awọn ika eniyan: nitori pe kii ṣe gbogbo eniyan ni o gbagbọ́.” (2 Tẹsalóníkà 3:2)
Ki ni nkan ti a ni ki a gbadura fun? A ni ki a gbadura pe ki Ọlọrun gba wa lọwọ awọn ika ati ọdaju eniyan. Eniyan ja si pe a ni ninu aye yi awọn ika ati ọdaju eniyan. Irufẹ awọn wọnyi a ma a ṣetan lati gbe igbesẹ-ki-gbesẹ lati han ẹnikẹni ti o ba ṣẹ wọn leemọ, bi o tilẹ jẹ wipe ko si ẹṣẹ kankan ninu ọrọ yowu ti o wa nilẹ. Lafikun, irufẹ awọn wọnyi ko ki i ṣaba gbẹbẹ. Ti wọn ba ti pinnu lati ṣe ẹnikan ni ewu, o di dandan ki wọn ṣe bẹẹ gẹgẹ, bi eyi yoo tilẹ gba gbogbo asiko aye wọn tabi gbogbo owo wọn. Nitorina, ayafi ti Ọlọrun ba pa wa mọ kuro lọwọ wọn, a ko le bọ lọwọ iwa buburu wọn.
Fun apẹrẹ, ọkunrin kan ti a n pe ni Hamani ṣetan lati pa Mọdẹkai ati gbogbo awọn Juu ti o wa labẹ ijọba Ọba Ahasiwerusi nitoripe Mọdẹkai ri fin. Ṣugbọn ẹnikan ṣoṣo ni Mọdẹkai. Ki wa lo de ti Hamani fi fẹ pa gbogbo awọn Juu nitori tirẹ? Idi ni pe ika ati ọdaju eniyan ni. Ti Mọdẹkai ati awọn eniyan rẹ ko ba si lọ gbadura si Ọlọrun pe ki O da si ọrọ naa ni, ọpọlọpọ wọn ni ko ba padanu ẹmi wọn nitori iwa buburu Hamani. (Wo: Ésítà 3-9)
Ti Ọba Hẹrọdu nkọ? Ọkunrin yi ran awọn jagun-jagun rẹ lati lọ pa gbogbo awọn ọmọ wẹwẹ ọdun meji ati awọn ti ko to bẹẹ ti o wa ni Betilẹhẹmu nitoripe o ṣa fẹ pa Jesu nigba ti o wa ni ọmọ irinsẹ. Ki ni idi? Ko fẹ ki o dagba di ọba awọn Juu. Niwọn igba ti ko si wa mọ ọmọde naa ti a n pe ni Jesu, o ba kuku pinnu lati pa gbogbo awọn ọmọ wẹwẹ ti o wa ni Bẹtilẹhẹmu, nibi ti a ti bi Jesu, ti wa ni iwọn ọjọ ori rẹ. Ti Ọlọrun ko ba wa da si ọrọ naa ni, a ko ba ti pa Jesu ki o to di pe yoo tilẹ ni anfaani lati ṣe iṣẹ ti Ọlọrun ran wa si aye lati ṣe. (Wo: Mátíù 2:1-18)
Ki ni koko ọrọ mi? Ohun naa ni pe awọn ika ati ọdaju eniyan bi Hamani ati Hẹrọdu si wa digbi ninu aye yi ati ni ayika wa. Satani si le lo wọn nigbakugba ati fun idi-ki-di lati kọlu wa. Ṣugbọn Ọlọrun le pa wa mọ kuro lọwọ wọn. Awa na, ẹwẹ, ko gbọdọ duro de igba ti eyi yowu ninu wọn yoo ma halẹ mọ wa ki a to kọ lati ma gbadura fun aabo Ọlọrun kuro lọwọ wọ. Aijẹbẹ, wọn le ti jẹ wa niya tan ki o to di pe a o ri aaye lati gbadura.
Nitorina, kọ bi a ṣe n gbadura lojoojumọ pe ki Ọlọrun ma pa ati iwọ ati ohun gbogbo ti o jẹ tirẹ mọ ni gbogbo igba kuro lọwọ awọn ika ati ọdaju eniyan ti o wa layika rẹ. Yoo si ri bẹ ẹ, ni orukọ Jesu. Amin.
Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.
Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)