Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu ọsu Òkúdù 2026. Adura mi si pe ki a ya aye rẹ ya ohunkohun ti o n di ọ lọwọ lati jẹ igbadun awọn ibukun rẹ ti a ti tu sori aye rẹ lẹkunrẹrẹ. Amin.
Wayi o, ọkan lara awọn nkan ti o ma n ṣaba di ifarahan awọn ibukun Ọlọrun ninu aye awọn eniyan rẹ lọwọ ni ki wọn ma ba awọn adari ti a yan le wọn lori ninu ijọ lo pọ ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ. Ki si ni ifẹ rẹ lori bi a ṣe n ba awọn adari ti o wa lori wa ninu ijọ ṣe pọ? Ifẹ rẹ ni a sọ fun wa ni kukuru ninu awọn ẹsẹ Iwe mimọ wọnyi:
“Ṣugbọn awa mbẹ̀ nyin, ará, lati mã mọ awọn ti nṣe lãla larin nyin, ti nwọn si nṣe olori nyin ninu Oluwa, ti nwọn si nkìlọ fun nyin; Ki ẹ si mã bu ọla fun wọn gidigidi ninu ifẹ nitori iṣẹ wọn. Ẹ si mã wà li alafia lãrin ara nyin.” (1 Tẹsalóníkà 5:12-13)
“Ẹ mã gbọ ti awọn ti nṣe olori nyin, ki ẹ si mã tẹriba fun wọn: nitori nwọn nṣọ ẹṣọ nitori ọkàn nyin, bi awọn ti yio ṣe iṣíro, ki nwọn ki o le fi ayọ̀ ṣe eyi, li aisi ibinujẹ, nitori eyiyi yio jẹ ailere fun nyin.” (Hébérù 13:17)
“Gẹgẹ bẹ̃li Oluwa si ṣe ìlana pe, awọn ti nwasu ihinrere ki nwọn o si ma jẹ nipa ihinrere.” (1 Kọ́ríntì 9:14)
Ki ni a ri nibiyi? Akọkọ, a ri wipe ifẹ Ọlọrun fun wa ni pe ki a bu ọla ti o ga fun awọn ti O yan gẹgẹ bi adari fun wa ninu ijọ. Eyi si gbọdọ farahan ninu bi a ti ṣe n ba wọn sọrọ ati bi a ti ṣe n ba wọn ṣe pọ. Ki ni idi? Ṣe nitoripe wọn san ju wa lọ niwaju Ọlọrun ni? Rara? Dipo bẹẹ, nitori iṣẹ rẹ ti wọn n ṣe ni aarin wa ni.
Wayi o, ko ki i wa ṣe kiki igba ti wọn ba n ṣe daradara si wa nikan ni a ni lati bọwọ fun wọn ni ọna yi; a ni lati bọwọ fun wọn pẹlu ni igba ti wọn ba n ba wa wi. Ọkan lara awọn idi ti Ọlọrun fi fi idi ijọba Dafidi mulẹ ni pe ko dẹkun lati ma a bọwọ fun Ọba Sọọlu gidigidi, bi o tilẹ jẹ wipe ọkunrin na ti ṣina. Ko yan asiko ti yoo bọwọ fun ati asiko ti ko ni bọwọ fun. Ti awa naa ba fẹ ki ibukun Ọlọrun fi idi mulẹ ninu aye wa, a ko gbọdọ yan igba ti a o ma bọwọ fun awọn adari ijọ wa. Dipo eyi, gbogbo igba ni a gbọdọ fi ọwọ ti o ga han fun wọn, nitoripe eyi ni ifẹ Ọlọrun fun wa. Ti a ba si wa ri eyi ti o n ṣiwawu ninu wọn, bi o tilẹ jẹ wipe a n bọwọ fun un, Ọlọrun yoo ṣe idajọ onitọun funrarẹ ni ọna tirẹ.
Nkan keji ti a fi han wa lori ifẹ Ọlọrun fun wa ni biba awọn adari wa ṣe pọ ni i ṣe pẹlu ki a tẹriba fun aṣẹ wọn. Ki ni eyi tunmọ si? O tunmọ si pe niwọn igba ti adari ijọ kan ba ti n dari rẹ ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun, nṣe ni ki o fi tọkantọkan ma a tẹle aṣẹ rẹ. Ki ni idi? Idi ni pe Ọlọrun yoo bere lọwọ rẹ bi o ti ṣe n ṣe. Irufẹ ijiyin wo ni yoo wa fun un nipa rẹ?
Nigbati Kora, Datani, Abiramu ati Oni gbimọ pọ lodi si Mose ati Aroni, Mose sọ fun Ọlọrun pe ki O ma tẹwọgba ọrẹ wọn. Ọlọrun ko si tẹwọgba. Yatọ fun iyẹn, O tun jẹ ki ilẹ lanu lati gbe ati awọn ati awọn ẹbi wọn mi laaye. Nitorina, bi o tilẹ jẹ wipe awọn naa ni ibukun Ọlọrun lori aye wọn, awọn ibukun wọnyi ko le pa wọn mọ kuro lọwọ idajọ rẹ. Eyi si waye nitori iha ti ko dara ti wọn kọ si awọn adari wọn. Ṣe iwọ naa wa ri idi ti a ṣe sọ fun wa pe ainitẹriba fun awọn adari ijọ wa ko le ṣiṣẹ gbe wa? (Wo: Númérì 16)
Siwaju si, ifẹ Ọlọrun ni fun wa lati ran awọn adari ijọ wa lọwọ pẹlu owo wa ati awọn nkan ti ara miran. Eyi ko si ki i ṣe nkan ti a o ma ṣe ni ẹkọọkan tabi nigbati a ba n woye pe ki wọn gba awọn akanṣe adura kan fun wa. Dipo eyi, o gbọdọ jẹ nkan ti a o fi ara wa jin lati ma a ṣe. Ọkankan ninu wa ko si ni awawi lati ma ṣe e. Idi si ni pe bi o tilẹ jẹ wipe ife omi kan pere ni a le ma a fun wọn loorekoore, Ọlọrun yoo tẹwọgba fun wa, yoo si tun pin wa lere fun un.
O wa ṣeni laanu pe, bi o tilẹ jẹ wipe ọpọ awọn ọmọ Ọlọrun ni a ti kọ ni awọn nkan wọnyi leralera, wọn ko ko ki i ṣiṣẹ le wọn lori. Ọkan lara awọn idi si ni yi ti ifarahan ìṣẹ́, ìjákulẹ̀ ati ailera ṣe wọpọ ninu ọpọ ijọ awọn eniyan Ọlọrun. Awa ni a n ṣiṣẹ lodi si ibukun rẹ ninu aye wa.
Wo o, ti o ko ba ri adari ijọ kan gẹgẹ bi ẹni ti ko lẹtọ si ọwọ, igbọran ati iranlọwọ rẹ, kuro ninu ijọ rẹ, ki o si lọ si ibi ti o ti le fi tọkan-tọkan bọwọ fun, gbọran si ati ṣe iranlọwọ fun adari ibẹ. Aijẹbẹ, nṣe ni iwọ yoo ma ṣiṣẹ lodi si iṣoriire ara rẹ. Adura mi si ni pe ki Ẹmi Ọlọrun dari rẹ sinu ironupiwada nibikibi ti o ba ti n kuna lori ọrọ yi ni kiakia. Amin.
Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin
Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)