Ìbàlẹ-ọkàn nínú túbú | Láti ọwọ́: Omotola Dunsin Babarinde | Ọjọ́: Ògún 09, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 15

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu idunnu ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu yi. Adura mi ni pe ki o ni iriri ibalẹ-ọkan Ọlọrun ti o kọja oye eniyan nibikibi ti ara ba ti n ni ọ ninu aye rẹ, ki ayọ rẹ ba a le kun. Amin.

Bi a ti ṣe n bẹrẹ ọsẹ yi, mo fẹ gba ọ niyanju pẹlu itan Pọọlu ati Sila ninu tubu ni ilu Filipi. Awọn ọkunrin wọnyi ni a mu, ti a na, ti a si tun sọ sinu tubu nitoripe wọn tu ẹrubinrin kan silẹ kuro lọwọ ẹmi eṣu ti o n lo o. Ṣugbọn, dipo ti eyi yoo fi fa irẹwẹsi si ọkan wọn, nṣe ni wọn bẹrẹ si ni gbadura, ti wọn si n yin Ọlọrun. Wo nkan ti Luuku sọ nipa eyi:

“Ṣugbọn larin ọganjọ Paulu on Sila ngbadura, nwọn si nkọrin iyìn si Ọlọrun: awọn ara tubu si ntẹti si wọn.” (Ìṣe Àpọ́sítélì 16:25)

Wayi o, bi gbogbo wa ti ṣe mọ, inu tubu jẹ ibi-ìdè, ibi inira ati ibi ti ireti ti pin. Sibẹsibẹ, Pọọlu ati Sila ni iriri ibalẹ-ọkan Ọlọrun ninu tubu. Itan wọn wa kọ wa pe awọn iṣẹlẹ aye wa ko nilo lati sakoso ọkan wa. Idi si ni pe lati ipasẹ idurotini Ọlọrun ni ibalẹ-ọkan otitọ ti n wa, eyi ti ko ni nkankan ṣe pẹlu ki iṣorọ ma wa.

Ki wa ni a le tipasẹ Pọọlu ati Sila kọ? Akọkọ ni pe ibalẹ-ọkan a ma wa nipasẹ gbigbẹkẹle Ọlọrun. Bi o tilẹ jẹ wi pe a na wọn, ti a si tun de wọn mọlẹ, Pọọlu ati Sila ko kun tabi ṣaroye. Dipo eyi, nṣe ni wọn gbẹkẹle Ọlọrun ninu inira wọn. Àìsáyà 26:3 sọ wipe, “Iwọ o pa a mọ li alafia pipé, ọkàn ẹniti o simi le ọ: nitoriti o gbẹkẹle ọ.” Nitorina, ti a ba fi igbẹkẹle wa sinu Ọlọrun, yoo fun wa ni ibalẹ-ọkan ti o peye.

Ekeji, a kọ nipasẹ wọn pe ibalẹ-ọkan a ma ja si iyin. Dipo ti wọn yoo fi ma kun sinu, Pọọlu ati Sila gbadura, wọn si tun kọ orin iyin si Ọlọrun lọganjọ oru. Ijọsin wọn fi han wa pe ọdọ Ọlọrun ni ibalẹ-ọkan ti ma n wa. Fílípì 4:7 sọ wipe, “Ati alafia Ọlọrun, ti o jù ìmọran gbogbo lọ, yio ṣọ ọkàn ati ero nyin ninu Kristi Jesu.” Eyi tunmọ si pe nibi ti ibalẹ-ọkan ba ti wa, ọkan wa yoo wa balẹ to lati yin Ọlọrun.

Ẹkẹta, a kọ lati ara nkan ti o ṣẹlẹ si Pọọlu ati Sila ninu tubu pe ibalẹ-ọkan a ma ṣiṣẹ fun itusilẹ agbara Ọlọrun. Bi wọn ti n yin Ọlọrun pẹlu ọkan ti o balẹ lẹkunrẹrẹ, Ọlọrun jẹ ki ilẹ mi titi, awọn ilẹkun tubu ṣi, a si ja gbogbo ide. Wa ranti wipe Sáàmù 34:19 sọ wipe, “Ọ̀pọlọpọ ni ipọnju olododo; ṣugbọn Oluwa gbà a ninu wọn gbogbo.” Nitorina, bi o ti wu ki isọro wa to, ibalẹ-ọkan lati ọdọ Ọlọrun le tu agbara rẹ silẹ lati yanju gbogbo wọn lẹyọkọọkan.

Ẹkẹrin, a kọ lati ara wọn pe iriri ibalẹ-ọkan lati ọdọ Ọlọrun le bukun fun awọn miran. Oluṣọ tubu ati idile rẹ gbagbọ ninu Jesu, wọn si di ẹni igbala nitori iriri ibalẹ-ọkan ti Pọọlu ati Sila ni ninu tubu. Mátíù 5:16, “Ẹ jẹ ki imọlẹ nyin ki o mọlẹ tobẹ̃ niwaju enia…” Nitorina, ti a ba fi aaye gba ibalẹ-ọkan lati ọdọ Ọlọrun lati jọba ninu aye wa, yoo jẹ ki awọn miran wa si ọdọ Ọlọrun nitori wa.

Ni akotan, ibalẹ-ọkan Ọlọrun wa fun wa pẹlupẹlu ni gbogbo asiko ti nkan nira. Adura ati iyin yoo fun igbagbọ wa ni okun ni asiko idanwo. Ọlọrun le sọ inu tubu di ile ẹri jijẹ. Igbagbọ rẹ ti ko yẹsẹ ni asiko iṣoro le dari awọn miran sọdọ Kirisii. Nitorina, bi o tilẹ wa ninu tubu loni, yala tubu aini, tubu aisan, tubu isoro ẹbi, tubu ijani-ni-tanmọ tabi tubu inunibini, ma ṣe sọ ireti nu. Ti o ba tẹsiwaju lati fi igbẹkẹle rẹ sinu Ọlọrun, ti o n gbadura si, ti o si n yin-in, yoo fun ọ ni ibalẹ-ọkan ati idande ni asiko ti o tọ.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *