Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu ayọ ti o ga ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ogun 2025. Adura mi ni pe ki ọrọ Ọlọrun ti o n fi igba gbogbo tọ ọ wa ninu ijọ yi ma kuna lati mu ifẹ rẹ ṣẹ ninu aye rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.
Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, igbakugba ti Ọlọrun ba sọrọ, nṣe ni yoo duro ti ọrọ naa lati mu wa si imuṣẹ (Jeremáyà 1:12). Ṣugbọn imuṣẹ ọrọ Ọlọrun ko ki i ṣadede waye. Iha ti awọn ti O n ba sọrọ ba kọ si ọrọ rẹ naa tun ṣe pataki. Aijẹbẹ, ọrọ rẹ le ma jẹ mimuṣẹ ninu aye wọn.
Fun apẹrẹ, bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun ṣe ileri lati fi ilẹ Kenani fun awọn ọmọ Isiraẹli, ọpọ ninu wọn ti o jade lati Ijibiti wa ni ko le wọ ibẹ. Ki ni idi? Idi ni pe iha ti wọn kọ si ileri Ọlọrun ko dara. Wọn ko gbagbọ pe Ọlọrun le mu ileri ti O ṣe fun wọn ṣẹ. Nitorina, nigba ti O sọ fun wọn pe ki wọn wọ ilẹ naa lọ lati gba a, wọn kọ lati ṣe bẹẹ. (Wo: Númérì 13-14)
Wayi o, nitoripe wọn kọ lati wọ ilẹ Kenani lati gba a nigba ti Ọlọrun sọ wipe ki wọn ṣe bẹ ẹ, Oun naa wa pinnu pe Oun ko ni fun wọn ni ilẹ naa mọ afi awọn ọmọ wọn. Ki wa ni o pada ṣẹlẹ si wọn? Nṣe ni wọn ranmu ninu aginju titi gbogbo wọn fi ṣegbe.
Nibakanna, a ri ọpọ Kirisitiẹni loni ti o n ranmu laye nitoripe wọn kọ lati tẹwọgba ọrọ Ọlọrun fun aye wọn, ki wọn ṣi ṣiṣẹ tọ ọ. Ki wa ni idi ti wọn fi kọ lati tẹwọgba ọrọ rẹ, ki wọn si ṣiṣẹ tọ ọ? Ibẹru jẹ ọkan lara awọn idi wọnyi. Ti awọn eniyan ba n bẹru bi nkan ti yoo tẹyin ki wọn ṣiṣẹ lori ọrọ Ọlọrun yọ yoo ṣe ri, wọn le ma ṣiṣẹ lori rẹ.
Lotitọ, ko si ẹnikẹni ninu wa ti o le fọwọ sọya sọ wipe bi nkan ti yoo tẹyin ki a ṣiṣẹ lori ọrọ Ọlọrun yọ yoo ṣe ri re e. Ṣugbọn ti a ba ni igbẹkẹle ninu pe Ọlọrun ko ni lailai doju ti wa, a o ṣiṣẹ lori ọrọ rẹ, bi o tilẹ jẹ wipe a ko mọ nkan ti yoo tẹyin rẹ jade. Ti a ba si ṣe eyi, o di dandan ki a ri ogo rẹ.
Igberega tun jẹ idi miran ti awọn kan ko ki i fi ṣiṣẹ lori ọrọ Ọlọrun. Awọn wọnyi, bi Ọba Sọọlu ati Ọba Asa, ro wipe awọn mọ ju Ọlọrun lọ ati wipe ete ti wọn san ju ki wọn fi igbẹkẹle wọn sinu rẹ, ki wọn si ṣe ohun yowu ti O ba sọ fun wọn pe ki wọn ṣe. Ṣugbọn bibeli sọ wipe omugọ Ọlọrun san ju ọgbọn eniyan lọ. O tun sọ fun wa pe ki a ma gbẹkẹle oye wa tabi ki a ro wipe a gbọn loju ara wa ni mimojuto ọrọ aye wa. Aijẹbẹ, bi o ti ṣe ri fun Sọọlu ati Asa, ko ni pẹ ti yoo fi han si awa naa pe omugọ ni ọgbọn wa. (Wo: 1 Sámúẹ́lì 15; 2 Kíróníkà 16; Ìwé Òwe 3:5-7; 1 Kọ́ríntì 1:25)
Lafikun, a ri awọn ti ko ki i ṣiṣẹ lori ọrọ Ọlọrun nitoripe wọn ko ki i farabalẹ tẹti si nkan ti o n sọ fun wọn. Ki ni idi? Idi ni pe ifẹ owo, ifẹ iyi, ifẹ faaji tabi ifẹ ipo ko jẹ ki wọn roju-raaye. Nkan ti ko wa ye wọn ni wipe awọn nkan wọnyi ko le fun wọn ni itẹlọrun laye. Ọlọrun nikan ni o le fun wọn ni itẹlọrun. Niwọn igba ti wọn ko si wa ni kọbiara si nkan ti O n sọ fun wọn, nṣe ni wọn o ma fi ayeraye le itẹlọrun kiri, ti wọn ko si ni ri.
Wayi o, mo le ma mọ idi ti iwọ naa ko ki i fi ṣiṣẹ lori ọrọ Ọlọrun ti o n tọ ọ wa bi o ti ṣe tọ. Ṣugbọn mo mọ wipe ti o ko ba ṣiṣẹ lori ọrọ rẹ, ko si bi aye rẹ ṣe fẹ fidi mulẹ ninu ifẹ rẹ. Ti o ba wa fẹ ki aye rẹ fi idi mulẹ ninu ifẹ rẹ, gbe ibẹru, igberaga tabi ohunkohun ti ko jẹ ki o roju-raaye ti ṣẹgbẹ kan, ki o ba a le kọbiara si gbigbọ ati ṣiṣe ọrọ Ọlọrun ni ẹkunrẹrẹ. Njẹ ki o gba okun lati ṣe eyi ni kiakia, ki aye rẹ ba a le da ohun gbogbo ti Ọlọrun fẹ ki o da. Amin.
Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.
Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)