Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o gbẹyin oṣu Ọ̀wàrà 2026. Adura mi ni pe a ko tun ni lailai fi awọn nkan ti o nilo fun iṣerere rẹ laye pamọ fun ọ mọ ni abala yowu ti o le wa laye, ni orukọ Jesu. Amin.
Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ti Ọlọrun ko ba ṣi oju awọn eniyan si awọn nkan ti wọn ni lati ṣe lati ni iriri alaafia ati iṣerere, ki wọn ba a le bẹrẹ si ni ṣe wọn, wọn le fi gbogbo ọjọ aye wọn ma a tiraka, ki wọn si ma ni iriri alaafia ati iṣerere. Fun apẹrẹ, ti Ọlọrun ko ba ṣi oju Ruutu ni asiko, lẹyin igba ti o ti padanu ọkọ rẹ, lati bẹrẹ si ni gbe igbesẹ ti yoo yọri si imupadabọsipo ati igbe aye alaafia ati iṣoriire fun-un, a le ma lailai gbọ nkankan nipa rẹ. (Wo: Rúùtù 1)
Ṣugbọn Ọlọrun ṣi oju rẹ, lakọkọ, lati kọ awọn oriṣa awọn eniyan rẹ silẹ ati lati tẹwọgba a gẹgẹ bi Ọlọrun rẹ. Lafikun, nigba ti o dabi ẹni pe ko mu ọgbọn lọwọ lati tẹle iya-ọkọ rẹ ati lati ma a toju rẹ, Ọlọrun ṣi oju ọkan rẹ lati ri wipe ṣiṣe bẹẹ gẹgẹ ni o tọ fun un. O si ṣe bẹẹ.
Wayi o, nitoripe o fi si ọkan rẹ lati tẹle iya-ọkọ rẹ, Naomi, pada wa si ilẹ Isiraẹli lati le ma a sin Ọlọrun ati lati mojuto iya arugbo yi i, Ọlọrun ru ọkan iya naa soke lati dari rẹ lati gbe igbesẹ ti yoo yi ohun gbogbo pada si rere fun un. Wo diẹ lara nkan ti bibeli sọ lori eyi:
“Ni ọjọ kan, Naomi, iya ọkọ Rutu wi fun un pe, ‘Ọmọbinrin mi, njẹ ko yẹ ki emi ba ọ wa ile ọkọ miiran, nibi ti wọn yoo ti le e maa tọju rẹ?” (Rutu 3:1)
Njẹ o ri bayẹn? Naomi fi si ọkan rẹ lati ri daju pe Ruutu, ẹni ti o ti padanu ọkọ rẹ ni rewerewe ati ẹni ti ko ti lọmọ laye, gba imupadabọsipo ati pe a fi a fi idi rẹ mulẹ sinu ile ifẹ, ayọ, alaafia ati iṣerere. Ọlọrun si fun un ṣe. Nitorina, Ruutu di ọkan lara awọn iya-nla Dafidi ati Jesu Oluwa wa. (Wo: Ruutu 3-4)
Ṣugbọn ki ni o fa ti Naomi ṣe fi si ọkan lati ṣe eyi fun Ruutu? Idi ni pe Ruutu funrarẹ gan dara si i. Yatọ si pe Ruutu ti gba Ọlọrun Isiraẹli gẹgẹ bi Ọlọrun otitọ, ti o si ti ṣetan lati sin in fun iyoku ọjọ aye rẹ, o tun boju aanu wo Naomi, ẹni ti o ti padanu ọmọkunrin rẹ meji, ti ko si tun ni ọmọ-ọmọ kankan ti o le ma a mojuto o. Idi ni yi ti o ṣe duro ti i nigba ti wọn pada de ilẹ Isiraẹli, ti o si n tọju rẹ, dipo ti yoo fi lọ fẹ ọkunrin miran lẹsẹkẹsẹ. Niwọn igba ti Naomi funrarẹ naa ko si ki ṣe ẹnikan ti o mọ tara rẹ nikan, ko pẹ rara ti o fi bẹrẹ si ni ṣiṣẹ lori bi inu Ruutu naa yoo ṣe pada dun.
Ki wa ni koko nkan wọnyi? Oun naa ni pe nipa fifi tọkan-tọkan ran awọn ti o wa ninu aye wa ti wọn nilo iranlọwọ lotitọ lọwọ, a le ma a la ọna fun aye awa tikara wa lati fi idi mulẹ sinu alaafia ati iṣerere. Awọn ti a n ran lọwọ le ma dabi ẹni ti o le gbe nkankan ti o ṣe pataki ṣe lori aṣeyọri ati ibalẹ-ọkan wa laye, gẹgẹ bi Naomi ko ṣe dabi ẹni ti o le gbe nkan rere kankan ṣe lori aye Ruutu. Ki a tilẹ sọ otitọ, oun funrarẹ sọ fun Ruutu ki wọn to kuro ni ilẹ Moabu pe oun ko ni nkan rere kankan ti oun le ṣe fun mọ. Sibẹsibẹ, Ruutu tẹle. Ki ni idi? Idi ni pe ko fi ọkan si nkan ti iya yi le ṣe fun oun bikoṣe nkan ti oun le ṣe lati mu aye rọrun fun iya naa. Bi Ọlọrun si ti wa jẹ ki ọrọ lọ, Naomi yi ni o wa papa dari rẹ sinu ile alaafia, ayọ ati ọpọlọpọ ohun rere gbogbo.
Nitorina, ma di oju rẹ si awọn nkan ti Ọlọrun n fi han ọ nipa awọn ti o wa ni ayika rẹ ti o le ran lọwọ, ti o le jẹ ki aye rọrun si fun wọn. Awọn wọnyi le jẹ awọn agbalagba kan ti o wa ni ayika rẹ, awọn ọmọde adugbo, awọn kan ninu ẹbi tabi ninu ijọ tabi awọn akẹgbẹ rẹ lẹnu iṣẹ tabi ni ile iwe. Irufẹ ẹni yowu ti wọn le jẹ, ṣe amulo ti o peye awọn anfaani ti Ọlọrun n fun ọ lati jẹ ki aye rọrun si fun wọn. Idi si ni pe o le ma a mọ ọna ti Ọlọrun le gba lo awọn nkan ti o n ṣe wọnyi lati mu aye rọrun fun iwọ naa pẹlu, yala loni tabi ni ọjọ iwaju.
Lafikun, ti Ọlọrun ba n lo ẹnikẹni lati mu aye rọrun fun ọ, ma ya alanikanjọpọn ninu ibaṣepọ rẹ pẹlu wọn. Ma fi oju si kiki nkan ti o le ti ara wọn jere. Nṣe ni ki iwọn naa ma a ronu nipa nkan ti awọn naa le ti ara rẹ jere. Ma a ronu nipa awọn nkan ti iwọ naa le ṣe lati mu aye rọrun si fun wọn. Aijẹbẹ, ti o ba to asiko kan, Ọlọrun le ti iẹlkun iranwọ ti o n rigba nipasẹ wọn. Eyi si le e pa ọ lara lọna ti o ga. Nitorina, jẹ ki igbayegbadun awọn ti igbayegbadun rẹ jẹ logun jẹ iwọ naa logun. Njẹ ki Ọlọrun ma a fi igba gbogbo kun aye rẹ pẹlu isinmi. Amin.
Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.
Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)