AKỌRI: ILANA FUN IRANWỌ GBIGBA NINU IJỌ AYỌKA: 1Timoti 5:3-16 | Paito J.O. Lawal

ỌJỌRU 24, BELU 2021

AKỌSORI: “Bi obinrin kan ti o gbagbọ ba ni awọn ibatan ti i ṣe opo, ẹ jẹ ki o maa ran wọn lọwọ, ki o ma si ṣe di ẹru naa le ijọ, ki wọn ki o le maa ran awọn ti i ṣe opo nitootọ lọwọ.” (1Timoti 5:16)

ỌRỌ AKỌSỌ
Bi a ti ṣe ri ni inu bibeli, ko si alaini kankan ninu awọn ọmọ Ọlọrun ti o kọkọ gbagbọ ninu Jesu ni igba aye awọn Apọsiteli akọkọ (Iṣe Apọsiteli 4:32-34). Ki si ni idi? Idi ni pe gbogbo wọn, paapaa julọ awọn ti a le pe ni ọlọrọ laarin wọn, n ran ara wọn lọwọ pẹlu awọn nkan ini wọn. Ọpọ ni o ta nkan ini wọn ni akoko yi, ti wọn si fun awọn apọsiteli ni owo ti wọn n pa nibẹ, ki wọn ba le lo wọn lati ran awọn alaini arin wọn lọwọ. Nigba ti o si ṣe, gbogbo wọn ti wọn gbagbọ kuro ni ipo alaini si ipo ẹni ti o ni anito ati aniṣẹku. Eyi si n jẹ ki o ye wa pe o ṣeeṣe ni ijọ wa kọọkan loni ki gbogbo wa ti a jẹ ọmọ Ọlọrun wa ni ipo ẹni ti o ni anito ati aniṣẹku. Awa naa kan nilo lati tọ ipasẹ awọn aṣaaju wa ni, ki a si fi ara wa jin lati ran ara wa lọwọ de ibi ti a o ti le sọ pe ko si alaini kankan ni aarin wa. Amọ ṣa o, ti a ko ba mọ ọna ti o tọ lati ṣe eleyi, o ṣeeṣe ki ififunni wa tabi iran ara wa lọwọ ma mu ete tabi erongba wa wa si imuṣẹ.

Bi a ti ṣe mọ, ọpọ ni o ti ri oniruuru iranwọ gba ninu ijọ ti ko si ja mọ nkankan fun wọn. Ọpọ ni a ti fun ni owo fun okowo tabi lati lọ si ile-ẹkọ, ti wọn si fi gbogbo nkan ti a fun wọn ṣofo. Awọn miran kan tilẹ pa irọ gba iranwọ ninu ijọ ni, ti wọn si wa jẹ ki awọn ti o ran wọn lọwọ ti ika abamọ bọ ẹnu. Idi si niyi ti o fi jẹ pe ọpọ ijọ Ọlọrun loni ni ko ki fi taratara kọbiara si ṣiṣe etọ iranwọ fun awọn ọmọ ijọ wọn. Mo ti lẹ ti gbọ lẹnu ẹnikan ri pe awọn adari ijọ kan sọ wipe, “Ṣọọṣi ko ki i ṣe baba keresi ti o ma n pin ẹbun ọfẹ.” Eyi si bi ẹni ti o gbọ ọrọ yi ninu gidigidi, to bẹẹ gẹẹ ti o fi sọ wipe, “Ti ṣọọṣi ko ba ki i ṣe baba keresi, ta wa ni o yẹ ki o jẹ baba keresi?”

Ti a ba si wo nitootọ, ko da bi ẹni pe nkan ti o buru ni ti ijọ Ọlọrun naa ba n ṣe bi baba keresi. Ṣugbọn ti a ba fi ẹsẹ ọrọ Ọlọrun tọ ọ, a o ri pe ijọ Ọlọrun ko ki i ṣe baba keresi ni tootọ, ti o kan ma n pin ẹbun lọfẹ lofo, lalai fi ti iru eni yowu ti o tọ ọ wa ṣe. Ka tilẹ sọ otitọ, baba keresi gan ti n fi ọgbọn ṣe bayi o. Awọn ti o ba sanwo lati wo o nikan ni o n pin ẹbun fun. Awọn ti ko ba sawọn iworan ko ni ri soju debi pe wọn yoo tilẹ gba ẹbun lọwọ rẹ. Eyi ko wa tunmọ si pe awọn ti o ba fi owo wọn mọ ijọ nikan ni o yẹ ki ijọ Ọlọrun ma ran lọwọ ni igba iṣoro tabi ipọnju. Ko tunmọ si rara pe awọn ti o ba n da idamẹwa ati ọrẹ deede nikan naa ni o yẹ fun iranwọ ijọ. Dipo eyi, o tunmọ si pe ilana wa ninu bibeli ti ijọ Ọlọrun gbọdọ ma tẹle ti wọn ba fẹ ṣe iranwọ fun ẹnikẹni, paapaa julọ ninu ijọ.

ILANA FUN IRANWỌ GBIGBA NINU IJỌ
Lakọkọ naa, a gbọdọ mọ pe ojuṣe wa ni gẹgẹ bi ijọ Ọlọrun kọọkan lati ma ran ara wa lọwọ nipa ti ẹmi ati nipa ti ara. Nitori naa, ko bojumu rara, ko si tun fi han pe a gbagbọ ninu Jesu nitootọ ati pe ifẹ rẹ n gbe inu ọkan wa ti a ba n wo awọn ara wa ti o wa ni ipo aini niran, ti a ko si gbe igbesẹ kankan lati ran wọn lọwọ nigba ti a wa ni ipo lati ṣe bẹẹ (Jemisi 2:14-17; 1Johanu 3:16-18). Amọ sa o, bi mo ṣe ti sọ siwaju, a gbọdọ mọ awọn ilana ti a la kalẹ sinu bibeli lori ọna ti a gbọdọ tẹle lati ma ran ara wa lọwọ ninu ijọ. Aijẹbẹ ifẹ Ọlọrun le ma wa si imuṣẹ nipasẹ iranwọ ti a ba n fun ara wa.

Ki wa ni awọn ilana ti a gbọdọ tẹle? Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, iwọnyi ni pataki julọ lara awọn ilana naa:

  • A gbọdọ ri daju pe ọmọ Ọlọrun ni ẹni ti a fẹ ran lọwọ: Ṣe awọn ọmọ Ọlọrun nikan ni o yẹ ki awọn Kirisitẹni ma ran lọwọ? Rara o! Bibeli sọ wipe, “Njẹ bi a ti n ri akoko, ẹ jẹ ki a maa ṣoore fun gbogbo eniyan, ati paapaa fun awọn ti i ṣe ara wa ninu igbagbọ.” (Galatia 6:10) Yatọ si eyi, o tun sọ wipe, “ Ṣugbọn bi ẹnikẹni ko ba pese fun awọn ibatan rẹ, paapaa fun idile rẹ, o ti ṣẹ ohun naa ti a gbagbọ, o si buru ju alaigbagbọ lọ.” (1Timoti 5:8) Nitori naa, ko ki i ṣe awọn ti o jẹ ọmọ Ọlọrun nikan ni o yẹ ki a ma ran lọwọ gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun. Gbogbo awọn ti Ọlọrun ba fun wa ni aye ati anfaani lati ran lọwọ ni a gbọdọ ma ran lọwọ. Ṣugbọn, a gbọdọ ri daju pe a kọkọ mojuto ile wa tabi idile wa ki a to a ṣe eleyi. Aijẹbẹ, a o jẹbi niwaju Ọlọrun. Yatọ si eyi, a tun gbọdọ mu riran awọn ọmọ Ọlọrun ti o wa ni ayika wa lọwọ, paapaa julọ awọn ọmọ ijọ wa. A si ri pe bibeli fi idi rẹ mulẹ pe a gbọdọ mu riran awọn ọmọ Ọlọrun ti a jọ n ṣepọ ni pataki ju riran awọn ti ko ki i ṣe ọmọ Ọlọrun lọwọ lọ. Idi si ni pe ẹya ara kan naa ni wa ninu Kirisiti Jesu (1Kọrinnti 12). Ko bojumu to lati pa awọn ọmọ ijọ wa ti o ṣe alaini ti, ki a si wa ma lo owo ti awọn ọmọ ijọ miran kojọ lati ma ṣe iranwọ fun awọn alaigbagbọ. Bi awọn aṣaaju wa ninu igbagbọ ti ṣe ṣe kọ ni yẹn. Nitorina, ki a to fun ẹnikẹni ni iranwọ ti o tọ si ọmọ Ọlọrun, paapaa julọ gẹgẹ bi ijọ Ọlọrun, a gbọdọ ri daju ṣaka pe ọmọ Ọlọrun ni ẹni bẹẹ ni tootọ. O si tunmọ si pe o gbọdọ kọja ọrọ ẹnu; a gbọdọ ri ninu iwa ati iṣe ẹni naa pe ọmọ Ọlọrun ti aye rẹ kun fun eso ẹmi ni. Aijẹbẹ, o ṣeeṣe ki ẹni naa ṣi oore-ọfẹ naa lo, ki o si tun mu ipalara ba ijọ Ọlọrun. Apẹẹrẹ eyi si kunlẹ jantirẹrẹ.
  • Iṣedari ijọ ni lati mọ nipa iranwọ ṣiṣe laarin ọmọ ijọ kan si omiran: Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ni igba ti ijọ Jesu bẹrẹ si ni pade, ti wọn si n ran ara wọn lọwọ, awọn apọsiteli ati awọn diakoni ni o n ṣe iṣakoso iṣẹ iranwọ yi. Awọn ni awọn ti o n ta nkan ini wọn n ko owo fun lati pin fun awọn ọmọ ijọ gẹgẹ bi aini ẹnikọọkan wọn ṣe ri. Idi si ni pe awọn ni o wa ni ipo lati tọpinpin, nipa ọgbọn Ẹmi mimọ ati oye ọrọ Ọlọrun, igbe aye ọmọ ijọ kọọkan ati lati mọ irufẹ iranwọ ti wọn nilo. Eyi tunmọ si pe ko ki i ṣe pe awọn eniyan kan dede n mu ẹni ti o ba wu wọn lati ran lọwọ. Ka sọ wipe bẹẹ lo ṣe ri ni, ọpọ ni ko ba kabamọ lori riran awọn ọmọ ijọ kan lọwọ. Bẹẹ si ni ọpọ ko ba tun ṣe kabamọ pe wọn gba iranwọ awọn kan. Yatọ si eyi, ikunsinnu ko ba wa laarin awọn ti wọn ro pe a ko ran awọn lọwọ to. A si ri lotitọ pe akoko kan wa ti awọn opo kan bẹrẹ si ni kun pe wọn awọn ti o n pin ounjẹ ojoojumọ fun wọn ti ti ẹlẹyamẹya ati ojuṣaaju bọ ọrọ naa. Eyi ni o si fa a ti awọn apọsiteli ṣe ni ki wọn yan awọn ti wọn kun fun Ẹmi mimọ, ti wọn si tun ni ọgbọn Ọlọrun ninu wọn lati ma mojutọ ọrọ naa. Nitori naa, ti a ko ba fẹ ṣe aṣiṣe ni riran awọn eniyan lọwọ ninu ijọ tabi ki a mu ki o fa ikunsinu tabi ipalara, a gbọdọ ṣe nipasẹ awọn adari wa ni. Awọn adari wa naa si gbọdọ ṣe ni ọna ti ojuṣaaju ko fi ni wọ ọ nipa fifi aye gba awọn ti o kun fun Ẹmi mimọ ati ọgbọn Ọlọrun lati ṣe amojuto ọrọ naa. (Wo: Iṣe Apọsiteli 4:34-37 & 6:1-7; 1Timoti 5:21)
  • Ẹni naa gbọdọ fi ara rẹ jin fun igbe aye iwa mimọ ati isin ninu ijọ: Yatọ si pe ki eniyan jẹ ọmọ Ọlọrun, bi mo ṣe sọ siwaju, o tun gbọdọ fi ara rẹ han ninu ijọ gẹgẹ bi ẹni ti o fi aye rẹ jin fun iwa mimọ ati sisin Ọlọrun. Fun apẹẹrẹ, Pọọlu, nigba ti o n fun Timoti ni alakalẹ lori awọn nkan ti o yẹ ki o wo ki o to ma ran opo kankan lọwọ pẹlu owo ijọ Ọlọrun, sọ fun pe, “Ma ṣe kọ orukọ opo ti o ba din ni ọgọta ọdun silẹ bi opo ti o yẹ fun iranlọwọ, oun si gbọdọ ti jẹ obinrin oloootọ si ọkọ rẹ, Ẹni ti a lee jẹrii rẹ fun iṣẹ rere, ti o ti tọ ọmọ rẹ bi o ti yẹ, ẹni ti o maa n gba alejo, ti o ti ṣe iranṣẹ fun awọn eniyan mimọ ninu irẹlẹ, ti o si maa n ran awọn ti a n pọn loju lọwọ, ẹni ti n lepa lati ṣe rere” (1Timoti 5:9-10) Pẹlu nkan ti Pọọlu sọ nibiyi, a ri pe ẹni yowu ti ijọ yoo ba ran lọwọ gbọdọ jẹ ẹni ti igbe aye ti o n gbe fi ogo fun Ọlọrun, ti oun naa si tun kun fun iṣẹ rere. Nitori naa, ẹni ti a ko ba le gbẹri rẹ jẹ pe igbe aye rẹ wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun ati pe o tun kun fi iṣe rere ni sisin ijọ Ọlọrun ko lẹtọ si iranwọ ijọ. Aijẹbẹ, ọpọ ni yoo ma lo iranwọ ti wọn gba ninu ijọ lati ṣe iranu tabi lati gbe igbe aye ti ko fi ogo fun Ọlọrun.
  • Awọn ti o n gba iranwọ ko gbọdọ jẹ ọlẹ tabi alaifẹkanṣe: Pọọlu, ninu lẹta rẹ si awọn ara Tẹsalonika kilọ fun wọn lati ma ṣe ran ẹnikẹni laarin wọn lọwọ lati jẹ ọlẹ tabi alainikanṣe. O tilẹ tun sọ siwaju si fun wọn pe ilana ti awọn fun wọn ni pe ẹnikẹni ti ko ba ṣiṣẹ ko lẹtọ si ounjẹ. Eyi tunmọ si pe ọlẹ, boya ninu ijọ ni o tabi ni ibomiran, ko lẹtọ si ounjẹ tabi iranlọwọ. Awọn ti wọn ṣetan lati ṣiṣẹ tọkantara ni iranwọ wulo fun. Idi si ni pe afojusun iranwọ ninu ijọ ki i ṣe lati pọn awọn kan loju ki a ba le tu awọn kan lara bikoṣe lati mu wa de ibi ti ko ti ni si alaini ni aarin wa. Eyi tunmọ si pe ti a ba ran ọ lọwọ loni, ki iwọ naa ba le ran ẹlomiran lọwọ lọla ni. Ti o ba wa ya ọlẹ, njẹ eyi yoo ṣeeṣe bi? Ko ni i ṣeeṣe. Abi ṣe o wa dara ki awọn kan ma fi tọkantara sin Ọlọrun ati fẹ awọn ara wọn pẹlu nkan ini wọn, ki awọn kan si ma fi imẹlẹ ati iwa ọlẹ jẹ igbadun laala wọn? Ko dara rara. Nitori naa, ijọ Ọlọrun ko lẹtọ lati fun ọmọ ijọ alapamaṣiṣẹ kankan ni owo iranwọ. (Wo: 2Kọrinnti 8:13-14; 2Tẹsalonika 3:6-15; 1Timoti 5:9-15)
  • Iranwọ ti o tọ si awọn arugbo ko gbọdọ lọ sọdọ awọn ọdọ: Nkan miran ti a tun fi lọlẹ fun wa ninu bibeli ni pe ko ki i ṣe gbogbo ọmọ ijọ naa ni o nilo iranwọ owo lati ọdọ ijọ. Yatọ si pe eniyan jẹ Kiristiẹni ti a le gba ẹri rẹ jẹ, niwọn igba ti o ba si jẹ ọdọ, ti o ṣi le ṣiṣẹ, ko yẹ ki a tun ma ran lọwọ bi arugbo. Eyi ko sọ wipe ki a ma ran lọwọ rara o, paapaa julọ ti ba wa ninu iṣoro. Amọ a gbọdọ ran lọwọ gẹgẹ bi ọdọ ni, ki i ṣe gẹgẹ bi arugbo ti ko ni ẹnikankan ti o le ran an lọwọ. Eyi si lo fa a ti Pọọlu ṣe sọ fun Timoti pe awọn opo ti ko ba i ti pe ọgọta ọdun ko yẹ ki o wa lori iwe awọn ti ijọ yoo ma fi owo ran lọwọ. Idi si nipe awọn wọnyi si le tun ọkọ ni, ki wọn si tun ma ṣiṣẹ lẹgbẹkan. Aijẹbẹ, a o kan ma ran awọn ọmọ ijọ wa lọwọ lati ya ọlẹ, atojubọle ati alainikannṣe ni. (Wo: 1Timoti 5:9-15)
  • Awọn ti o n gba iranwọ gbọdọ jẹ ẹni ko ni ẹbi ti o le ran wọn lọwọ: Yatọ si awọn ilana ti a ti mẹnuba nipa riran awọn ọmọ Ọlọrun lọwọ ninu ijọ, a tun gbọdo ri daju pe awọn ti a ba fẹ ran lọwọ jẹ awọn ti ko ni ẹbi tabi ara ti o gbagbọ tabi ti o ṣetan lati ran wọn lọwọ. Bi a ṣe fi ye wa ninu bibeli, awọn ti wọn ba ni ọmọ tabi ara ti o le ran wọn lọwọ ko nilo lati tun ma gba iranwọ ijọ Ọlọrun. O yẹ ki a jẹ ki awọn ọmọ wọn tabi ara wọn mọ ojuṣe wọn si wọn ni, ki wọn si maa ṣe e. Eyi tunmọ si pe awa ti a ba ni obi ninu ijọ ko yẹ ki a tun jẹ ki wọn di bukata ijọ. Nṣe ni o yẹ ki a ma mojuto wọn. Aijẹbẹ, asan ni igbagbọ wa ja si, a ko si san ju awọn alaigbagbọ lọ. Nitori naa, a gbọdọ kọ awọn ọmọ Ọlọrun lati ma ṣe jẹ ki awọn ara wọn ti o yẹ ki wọn maa tọju di bukata ijọ Ọlọrun. Idi si nipe eyi yoo fi aye silẹ fun ijọ lati ran awọn miran ti ko ni oluranlọwọ lọwọ. Amọ ti a ko ba jẹ ki eyi ye awọn ọmọ Ọlọrun, a o kan ri pe ijọ Ọlọrun bẹrẹ si ni ru ajaga ti ko yẹ ki o ru ni. Eyi yoo si ran ọpọ lọwọ lati ma gbe igbe aye ojukokoro ati ọkanjua. (Wo: 1Timoti 5:4-8&16)
  • Odiwọn iranwọ si ẹnikẹni gbọdọ wa lori oun ti ijọ ni dipo nkan ti ijọ ko ni: Ko si ẹnikẹni ti o le fun eniyan ni nkan ti ko ba ni. Idi si ni yi ti Ọlọrun fi jẹ ki o ye wa pe gbogbo fififunni wa gbọdọ da lori nkan ti a ni dipo nkan ti a ko ni (2Kọrinnti 8:12). Eyi wa jasi pe ti ijọ Ọlọrun ba fẹ ran ẹnikẹni lọwọ, iranwọ naa gbọdọ wa lori gbedeke nkan ti ijọ ni ni dipo eyi ti ko ni. Idi ni yi ti awọn ọmọ Ọlọrun ti o ba ni lọwọ daradara ṣe gbọdọ ma fi gbogbo igba fi owo tabi nkan iranwọ silẹ fun awọn ara wọn ninu ijọ. Ko ki i ṣe nkan ti o dara ni ki ijọ Ọlọrun ma jẹ gbese nitori pe wọn fẹ ran ọmọ ijọ kan lọwọ tabi nitori pe wọn ni awọn akanṣe iṣẹ kan. Ti a ba fẹ ki a ma ran awọn ọmọ ijọ wa lọwọ lọna ti o peye, nṣe ni ki awa naa bẹrẹ si ni ṣe awọn nkan ti yo jẹ ki o ṣeeṣe.

ỌRỌ IPARI
Riran awọn ọmọ Ọlọrun lọwọ nipa ti ara lati le da duro, ki wọn ma si ṣe wa ni ipo alaini ṣe pataki pupọ. Amọ ti a ko ba tẹle ilana bibeli lati ma ṣe eyi, ko si ni ki a ma kabamọ lori rẹ tabi ki a da rugudu silẹ ninu ijọ.

IBEERE

  • Bawo ni ẹkọ yi ṣe ṣe pataki to fun awọn ọmọ Ọlọrun?
  • Awọn nkan miran wo ni o le sọ pe a tun fi ẹsẹ wọn mulẹ ninu bibeli gẹgẹ bi ilana ti o yẹ ki a tẹle lati ran awọn ọmọ Ọlọrun lọwọ?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *