Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Erele 2022. Adura mi fun ọ si ni pe ki o ma fi gbogbo igba gba okun lati ọdọ Ẹmi Ọlọrun lati jẹ olotitọ si ati lati ma ṣe bojuwẹyin rara titi di opin igba yi. Amin.
Gẹgẹ bi Jesu Oluwa wa ti ṣe fi ye we yekeyeke, kiki awọn ti o ba duro ṣinṣin ninu igbagbọ wọn de opin ni yoo ni iriri igbala ayeraye (Matiu 24:13). Yatọ si eyi, awọn apọsiteli rẹ naa tun sọ nkankanna ninu awọn akọsilẹ wọn. Awọn naa fi han wa pe kiki awọn ti o ba duro ṣinṣin ninu igbagbọ wọn titi de opin ohun gbogbo ni onigbagbọ ododo ati alabapin ninu Kirisiti (Kolose 1:21-23; Heberu 3:6&14). Nitorina, irinajo wa pẹlu Ọlọrun ko yẹ ko jẹ foniku-fọlande tabi eyi ti a o rin fun igba diẹ. Dipo eyi, nṣe ni o yẹ ki o jẹ eyi ti a o rin lati ibẹrẹ de opin. Eyi wa jasi pe a ko gbọdọ dẹyin tabi bojuwẹyin. Nṣe ni a gbọdọ ma tẹsiwaju ninu rẹ titi de opin ohun gbogbo.
Woo, ewu wa ninu ki a dẹyin ninu irinajo yi. Ewu si tun n bẹ ninu ka bojuwẹyin naa. Jesu Oluwa wa sọ pe, “Ranti aya Lọọti.” (Luuku 17:32) Ki ni ki a ranti nipa aya Lọọti? Dajudaju, ipe yi ko ki i ṣe fun wa lati ranti pe obinrin Lọọti ni arabinrin yi jẹ tabi pe o bi awọn ọmọbinrin melokan fun un. Dipo eyi, ipe naa ni fun wa lati ranti iṣẹlẹ kan ti o ṣẹlẹ laye rẹ, eyi ti o kọ wa lati ma bojuwẹyin lẹyin igba ti a ba ti dahun ipe lati ba Ọlọrun ni ajọṣepọ.
Aya Lọọti, gẹgẹ bi ọkọ rẹ pẹlu, ni a kilọ fun nipasẹ awọn angẹli ti Ọlọrun ran lati pa Sodomu ati Gomora run lati sa asala fun ẹmi rẹ ati lati ma ṣe bojuwẹyin fun idi kankan. Ọna ti Ọlọrun n gba lati fi aanu han arabinrin yi niyi, ki o ma ba di ẹni iparun pẹlu awọn ika eniyan Sodomu ati Gomora. Ṣugbọn arabinrin yi ṣe aigbọran si aṣẹ kekere yi, o si bojuwẹyin.
Wayi o, bibojuwẹyin rẹ ṣeeṣe ki o dabi nkan ti ko lewu rara fun un lati ṣe. Nkan ti mo n sọ ni pe bibojuwẹyin rẹ yi lati mọ nkan ti o ṣẹlẹ si Sodomu ati Gomora ko dabi ki o ma ba wọn kopa ninu ẹṣẹ agbere, ole-jija tabi ifẹkufẹ ti ko dọgba. Ṣibẹsibẹ, ṣiṣe bẹẹ mu ijiya lọwọ wa fun un. Lẹsẹkẹsẹ naa ni o di ọwọn iyọ, ti ko si le de ebute rẹ ti o n lọ mọ fun aabo. Nitorina, bibojuwẹyin fun aya Lọọti ko yatọ rara si kikopa ninu ẹṣẹ awọn ara Sodomu ati Gomora. (Wo: Jẹnẹsisi 19)
Ṣugbọn ki lo jẹ ko bojuwẹyin? A ko la a fun wa ninu bibeli. Ohun yowu ti o jẹ, nkan naa jẹ ki o padanu ẹmi rẹ, ki o si tun kuna lati de ebute aabo ti o n lọ. Nibakannaa, oniruuru nkan ni o le jẹ ki awa naa bojuwẹyin wo igbe ayẹ ẹṣẹ ati aigbọran si Ọlọrun ti a ti kọ silẹ. Ti a ba si wa fi aye gba ọkankan lara wọn lati jẹ ki a bojuwẹyin, o ṣeeṣe ki a di wa lọwọ lati tẹsiwaju ninu irinajo igbagbọ wa lati ni iriri igbala ayeraye.
Nitorina, a gbọdọ ma fi gbogbo igba pa ọkan ati aye wa mọ kuro lọwọ awọn ero ati awọn eniyan ti o ba n fi ọpọ igba fẹ jẹ ki a bojuwẹyin, ki a si tun pongbẹ fun igbe aye ofo atijọ ti a ti pati. Bẹẹni, a gbọdọ daabo bo ara wa kuro lọwọ ohunkohun tabi ẹnikẹni ti o ba n jẹ ki a fi gbogbo igba ṣafẹri igbe aye atijọ ti a ti kọ silẹ. Si ranti pe, gẹgẹ bi o ti ṣe ri ni ti aya Lọọti, bibojuwẹyin lati yọ lori igbe aye ẹṣẹ wa atẹyinwa le buru jọjọ bi ki a ma gbe ninu ẹṣẹ lọwọlọwọ yi. Ibikibi ti eyi ba si ti ri bẹ, awa naa le reti irufẹ ijiya ẹṣẹ ti awọn ti o n dẹṣẹ lọwọlọwọ ba n jẹ ninu aye wọn. Iru ijiya ti eyi wa le jẹ ni n ko le sọ fun ọ. Ṣugbọn mo le sọ fun ọ pe ki o ranti aya Lọọti.
Ki o ni ọsẹ aladun.
Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
